-
Dáníẹ́lì 5:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ọkùnrin kan* wà nínú ìjọba rẹ tó ní ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́. Nígbà ayé bàbá rẹ, ó ní ìmọ̀, ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n, bí ọgbọ́n àwọn ọlọ́run.+ Ọba Nebukadinésárì, bàbá rẹ fi ṣe olórí àwọn àlùfáà onídán, àwọn pidánpidán, àwọn ará Kálídíà* àti àwọn awòràwọ̀;+ ohun tí bàbá rẹ ṣe nìyí, ọba. 12 Torí Dáníẹ́lì, ẹni tí ọba pè ní Bẹtiṣásárì,+ ní ẹ̀mí tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye láti túmọ̀ àwọn àlá, láti ṣàlàyé àwọn àlọ́, kó sì wá ojútùú sí ohun tó bá lọ́jú pọ̀.*+ Jẹ́ kí wọ́n pe Dáníẹ́lì wá, ó sì máa sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”
-