ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Jákọ́bù 1:1-5:20
  • Jémíìsì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jémíìsì
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jémíìsì

LẸ́TÀ JÉMÍÌSÌ

1 Jémíìsì,+ ẹrú Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi Olúwa, sí ẹ̀yà méjìlá (12) tó wà káàkiri:

Mo kí yín!

2 Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀,+ 3 kí ẹ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó máa mú kí ẹ ní ìfaradà.+ 4 Àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì máa ṣe ohun tó tọ́ nínú ohun gbogbo, láìkù síbì kan.+

5 Torí náà, tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run,+ ó sì máa fún un,+ torí ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn, kì í sì í pẹ̀gàn*+ tó bá ń fúnni. 6 Àmọ́ kó máa fi ìgbàgbọ́ béèrè,+ kó má ṣiyèméjì rárá,+ torí ẹni tó ń ṣiyèméjì dà bí ìgbì òkun tí atẹ́gùn ń fẹ́ káàkiri. 7 Kódà, kí ẹni náà má rò pé òun máa rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà;* 8 aláìnípinnu ni onítọ̀hún,+ kò sì dúró sójú kan ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.

9 Àmọ́ kí arákùnrin tó rẹlẹ̀ máa yọ̀* torí a gbé e ga,+ 10 àti ọlọ́rọ̀ torí a ti rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,+ torí ó máa kọjá lọ bí òdòdó inú pápá. 11 Bí oòrùn ṣe máa ń mú ooru tó ń jóni jáde tó bá yọ, tó sì máa mú kí ewéko rọ, tí òdòdó rẹ̀ á já bọ́, tí ẹwà rẹ̀ tó tàn sì máa ṣègbé, bẹ́ẹ̀ náà ni ọlọ́rọ̀ máa pa rẹ́ bó ṣe ń lépa ọrọ̀.+

12 Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fara da àdánwò,+ torí tó bá rí ìtẹ́wọ́gbà, ó máa gba adé ìyè,+ tí Jèhófà* ṣèlérí pé òun máa fún àwọn tí ò yéé nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.+ 13 Tí àdánwò bá dé bá ẹnikẹ́ni, kó má ṣe sọ pé: “Ọlọ́run ló ń dán mi wò.” Torí a ò lè fi ibi dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò. 14 Àmọ́ àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.*+ 15 Tí ìfẹ́ ọkàn náà bá ti gbilẹ̀,* ó máa bí ẹ̀ṣẹ̀; tí ẹ̀ṣẹ̀ náà bá sì ti wáyé, ó máa yọrí sí ikú.+

16 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣì yín lọ́nà. 17 Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé wá láti òkè,+ ó ń wá látọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá,+ ẹni tí kì í yí pa dà, tí kì í sì í sún kiri bí òjìji.*+ 18 Ìfẹ́ rẹ̀ ni pé kó fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ mú wa wá,+ ká lè di oríṣi àkọ́so kan nínú àwọn ohun tó dá.+

19 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ mọ èyí: Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀, kí wọ́n lọ́ra láti sọ̀rọ̀,+ kí wọ́n má sì tètè máa bínú,+ 20 torí ìbínú èèyàn kì í mú òdodo Ọlọ́run wá.+ 21 Torí náà, ẹ mú gbogbo èérí àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìwà burúkú* kúrò,+ kí ìwà tútù yín sì mú kí ọ̀rọ̀ tó lè gbà yín là* fìdí múlẹ̀ nínú yín.

22 Àmọ́, ẹ máa ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ,+ ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán, kí ẹ wá máa fi èrò èké tan ara yín jẹ. 23 Torí tí ẹnikẹ́ni bá ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ tí kò ṣe é,+ ẹni yìí dà bí èèyàn tó ń wo ojú ara rẹ̀* nínú dígí. 24 Torí ó wo ara rẹ̀, ó lọ, ó sì gbàgbé irú ẹni tí òun jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 25 Àmọ́ ẹni tó bá ń fara balẹ̀ wo inú òfin pípé+ tó jẹ́ ti òmìnira, tí kò sì yéé wò ó, kì í ṣe olùgbọ́ tó ń gbàgbé, àmọ́ ó ti di olùṣe iṣẹ́ náà; ohun tó ń ṣe á sì máa múnú rẹ̀ dùn.+

26 Tí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń jọ́sìn Ọlọ́run,* àmọ́ tí kò ṣọ́ ahọ́n rẹ̀ gidigidi,*+ ṣe ló ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, asán sì ni ìjọsìn rẹ̀. 27 Ìjọsìn* tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run àti Baba wa nìyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ aláìlóbìí+ àti àwọn opó+ nínú ìpọ́njú wọn,+ ká sì máa pa ara wa mọ́ láìní àbààwọ́n nínú ayé.+

2 Ẹ̀yin ará mi, bí ẹ ṣe di ìgbàgbọ́ Jésù Kristi, Olúwa wa ológo mú, ṣé kì í ṣe pé ẹ tún ń ṣe ojúsàájú?+ 2 Tí ẹnì kan bá wá sí ìpàdé yín, tó wọ àwọn òrùka wúrà sí ìka rẹ̀, tó sì wọ aṣọ tó dáa gan-an, àmọ́ tí tálákà kan tó wọ aṣọ tó dọ̀tí náà wọlé wá, 3 ṣé ẹ máa fi ojúure wo ẹni tó wọ aṣọ tó dáa gan-an, tí ẹ máa sọ pé, “Jókòó síbi tó dáa yìí,” tí ẹ sì máa wá sọ fún tálákà náà pé, “Ìwọ wà lórí ìdúró” tàbí, “Jókòó síbẹ̀ yẹn lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi”?+ 4 Tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé kì í ṣe pé kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ti wà láàárín yín nìyẹn,+ tí ẹ sì ti di adájọ́ tó ń dá ẹjọ́ burúkú?+

5 Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n. Ṣebí àwọn tí aráyé kà sí tálákà ni Ọlọ́run yàn pé kí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́+ àti ajogún Ìjọba náà, èyí tó ṣèlérí fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?+ 6 Síbẹ̀, ẹ ti tàbùkù sí tálákà. Ṣebí àwọn ọlọ́rọ̀ ló ń ni yín lára,+ tí wọ́n sì ń fà yín lọ sí ilé ẹjọ́? 7 Ṣebí wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ rere tí ẹ̀ ń jẹ́? 8 Tí ẹ bá ń mú ọba òfin ṣẹ bó ṣe wà nínú ìwé mímọ́ pé, “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ,”+ ẹ̀ ń ṣe dáadáa gan-an ni. 9 Àmọ́ tí ẹ bá ṣì ń ṣe ojúsàájú,+ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ̀ ń dá, òfin sì ti dá yín lẹ́bi* pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.+

10 Torí tí ẹnikẹ́ni bá ń pa gbogbo Òfin mọ́ àmọ́ tó ṣi ẹsẹ̀ gbé nínú ọ̀kan, ó ti rú gbogbo òfin.+ 11 Torí ẹni tó sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,”+ ló tún sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn.”+ Nígbà náà, tí o ò bá ṣe àgbèrè àmọ́ tí o pààyàn, o ti di arúfin. 12 Ẹ máa sọ̀rọ̀ kí ẹ sì máa hùwà bí àwọn tí a máa fi òfin àwọn tó wà lómìnira* dá lẹ́jọ́.+ 13 Torí ẹni tí kì í ṣàánú kò ní rí àánú gbà nígbà ìdájọ́.+ Àánú máa ń borí ìdájọ́.

14 Ẹ̀yin ará mi, kí ni àǹfààní rẹ̀, tí ẹnì kan bá sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ àmọ́ tí kò ní àwọn iṣẹ́?+ Ìgbàgbọ́ yẹn ò lè gbà á là, àbí ó lè gbà á?+ 15 Tí arákùnrin tàbí arábìnrin èyíkéyìí ò bá láṣọ,* tí wọn ò sì ní oúnjẹ tó máa tó wọn jẹ lóòjọ́, 16 síbẹ̀ tí ẹnì kan nínú yín sọ fún wọn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà; kí ẹ rí aṣọ fi bora, kí ẹ sì yó dáadáa,” àmọ́ tí ẹ ò fún wọn ní ohun tí ara wọn nílò, àǹfààní kí ló jẹ́?+ 17 Bákan náà, ìgbàgbọ́ nìkan láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.+

18 Àmọ́ ẹnì kan lè sọ pé: “Ìwọ́ ní ìgbàgbọ́, èmí sì ní àwọn iṣẹ́. Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí láìsí àwọn iṣẹ́, màá sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ mi.” 19 O gbà pé Ọlọ́run kan ló wà, àbí? O ṣe dáadáa gan-an ni. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbà, jìnnìjìnnì sì bò wọ́n.+ 20 Àmọ́ ṣé o tiẹ̀ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ kò wúlò láìsí iṣẹ́, ìwọ èèyàn lásánlàsàn? 21 Ṣebí a ka Ábúráhámù bàbá wa sí olódodo nípa àwọn iṣẹ́ lẹ́yìn tó mú Ísákì ọmọ rẹ̀ lọ sórí pẹpẹ?+ 22 Ẹ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn kedere nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀, àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di pípé,+ 23 a sì mú ìwé mímọ́ náà ṣẹ tó sọ pé: “Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà,* a sì kà á sí òdodo fún un,”+ a sì wá ń pè é ní ọ̀rẹ́ Jèhófà.*+

24 Ṣé ẹ wá rí i pé àwọn iṣẹ́ la fi ń ka èèyàn sí olódodo, kì í ṣe ìgbàgbọ́ nìkan. 25 Bákan náà, ṣebí àwọn iṣẹ́ ló mú kí á ka Ráhábù aṣẹ́wó pẹ̀lú sí olódodo, lẹ́yìn tó gba àwọn òjíṣẹ́ lálejò, tó sì ní kí wọ́n gba ọ̀nà míì jáde?+ 26 Lóòótọ́, bí ara láìsí ẹ̀mí* ṣe jẹ́ òkú,+ bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.+

3 Ẹ̀yin arákùnrin mi, kí púpọ̀ nínú yín má ṣe di olùkọ́, torí ẹ mọ̀ pé a máa gba ìdájọ́ tó wúwo* jù.+ 2 Nítorí gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀* lọ́pọ̀ ìgbà.+ Tí ẹnì kan kì í bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ, á jẹ́ pé ẹni pípé ni, ó sì lè kó gbogbo ara rẹ̀ níjàánu. 3 Tí a bá fi ìjánu sí ẹnu àwọn ẹṣin kí wọ́n lè ṣègbọràn sí wa, gbogbo ara wọn là ń darí pẹ̀lú. 4 Ẹ tún wo àwọn ọkọ̀ òkun: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tóbi gan-an, tí atẹ́gùn tó le gan-an sì máa ń gbé wọn kiri, ìtọ́kọ̀ tó kéré gan-an la fi ń darí wọn síbi tí ẹni tó ń darí ọkọ̀ bá fẹ́ kó lọ.

5 Bẹ́ẹ̀ náà ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà ara tó kéré, síbẹ̀ ó máa ń fọ́nnu gan-an. Ẹ wo bí iná tí kò tó nǹkan ṣe lè jó igbó kìjikìji run! 6 Bákan náà, ahọ́n jẹ́ iná.+ Ahọ́n dúró fún ayé àìṣòdodo lára àwọn ẹ̀yà ara wa, torí ó máa ń sọ gbogbo ara di aláìmọ́,+ ó sì máa ń dáná sí gbogbo ìgbésí ayé* ẹ̀dá, iná Gẹ̀hẹ́nà* á sì sun òun náà. 7 Torí àwọn èèyàn máa ń kápá gbogbo ẹran inú igbó àti ẹyẹ àti ẹran tó ń fàyà fà* àti ẹ̀dá inú òkun, wọ́n sì ti kápá wọn. 8 Àmọ́ kò sí èèyàn tó lè kápá ahọ́n. Aláìgbọràn ni, ó sì ń ṣeni léṣe, ó kún fún májèlé tó ń pani.+ 9 Òun la fi ń yin Jèhófà,* Baba wa, síbẹ̀ òun la tún fi ń gégùn-ún fún àwọn èèyàn tí a dá ní “àwòrán Ọlọ́run.”+ 10 Ẹnu kan náà tí èèyàn fi ń súre ló tún fi ń gégùn-ún.

Ẹ̀yin ará mi, kò yẹ kó máa rí bẹ́ẹ̀.+ 11 Omi tó ṣeé mu* àti omi tó korò kì í jáde láti orísun kan náà, àbí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀? 12 Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ò lè mú èso ólífì jáde tàbí kí àjàrà mú èso ọ̀pọ̀tọ́ jáde, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?+ Bẹ́ẹ̀ ni omi iyọ̀ ò lè mú omi tó ṣeé mu jáde.

13 Ọlọ́gbọ́n àti olóye wo ló wà láàárín yín? Kó fi ìwà rere rẹ̀ hàn nínú bó ṣe ń fi ìwà tútù ṣe àwọn iṣẹ́ tó fi hàn pé ó gbọ́n. 14 Àmọ́ tí ẹ bá ń jowú gidigidi,+ tó sì ń wù yín láti máa fa ọ̀rọ̀,*+ ẹ má ṣe máa fọ́nnu,+ ẹ má sì máa parọ́ mọ́ òtítọ́. 15 Èyí kì í ṣe ọgbọ́n tó wá láti òkè; ti ayé ni,+ ti ẹranko àti ti ẹ̀mí èṣù. 16 Torí ibikíbi tí wọ́n bá ti ń jowú tí wọ́n sì ń fa ọ̀rọ̀,* ìdàrúdàpọ̀ àti gbogbo nǹkan burúkú máa ń wà níbẹ̀.+

17 Àmọ́, ọgbọ́n tó wá láti òkè á kọ́kọ́ jẹ́ mímọ́,+ lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà,+ ó ń fòye báni lò,+ ó ṣe tán láti ṣègbọràn, ó máa ń ṣàánú gan-an, ó sì ń so èso rere,+ kì í ṣe ojúsàájú,+ kì í sì í ṣe àgàbàgebè.+ 18 Bákan náà, ibi tí àlàáfíà bá wà+ la máa ń gbin èso òdodo sí fún àwọn tó ń wá àlàáfíà.*+

4 Ibo ni ogun àti àwọn ìjà tó wà láàárín yín ti wá? Ṣebí inú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tó ń bá yín* fínra ló ti wá?+ 2 Ó ń wù yín, síbẹ̀ ẹ ò ní in. Ẹ̀ ń pààyàn, ẹ ò sì yéé ṣojúkòkòrò, síbẹ̀ ọwọ́ yín ò tẹ̀ ẹ́. Ẹ̀ ń jà, ẹ sì ń jagun.+ Ẹ ò ní torí pé ẹ ò béèrè. 3 Nígbà tí ẹ sì béèrè, ẹ ò rí gbà torí ohun tí kò dáa lẹ fẹ́ fi ṣe, ṣe lẹ fẹ́ lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín.

4 Ẹ̀yin alágbèrè,* ṣé ẹ ò mọ̀ pé bíbá ayé ṣọ̀rẹ́ ń sọni di ọ̀tá Ọlọ́run ni? Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.+ 5 Àbí ẹ rò pé lásán ni ìwé mímọ́ sọ pé: “Ẹ̀mí tó ń gbé inú wa ń mú ká máa jowú ṣáá”?+ 6 Àmọ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ó ń fi hàn tóbi ju èyí lọ. Ìdí nìyẹn tí ìwé mímọ́ fi sọ pé: “Ọlọ́run dojú ìjà kọ àwọn agbéraga,+ àmọ́ ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.”+

7 Torí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run;+ àmọ́ ẹ dojú ìjà kọ Èṣù,+ ó sì máa sá kúrò lọ́dọ̀ yín.+ 8 Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.+ Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀,+ kí ẹ sì wẹ ọkàn yín mọ́,+ ẹ̀yin aláìnípinnu. 9 Ẹ banú jẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì sunkún.+ Kí ẹ̀rín yín di ọ̀fọ̀, kí ayọ̀ yín sì di ìbànújẹ́. 10 Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ojú Jèhófà,*+ ó sì máa gbé yín ga.+

11 Ẹ̀yin ará, ẹ má sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa ara yín mọ́.+ Ẹnikẹ́ni tó bá ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa arákùnrin kan tàbí tó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́. Tí o bá wá ń dá òfin lẹ́jọ́, o ò pa òfin mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ onídàájọ́ ni ọ́. 12 Ẹnì kan ṣoṣo ni Afúnnilófin àti Onídàájọ́ wa,+ ẹni tó lè gbà là, tó sì lè pa run.+ Àmọ́ ìwọ, ta ni ọ́ tí o fi ń dá ọmọnìkejì rẹ lẹ́jọ́?+

13 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ pé: “Lónìí tàbí lọ́la, a máa rìnrìn àjò lọ sí ìlú yìí, a máa lo ọdún kan níbẹ̀, a máa ṣòwò, a sì máa jèrè,”+ 14 bẹ́ẹ̀ sì rèé, ẹ ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́la.+ Torí ìkùukùu ni yín, tó máa ń wà fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà tí á pòórá.+ 15 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ sọ pé: “Tí Jèhófà* bá fẹ́,+ a máa wà láàyè, a sì máa ṣe tibí tàbí tọ̀hún.” 16 Àmọ́ ẹ̀ ń gbéra ga, ẹ sì ń fọ́nnu. Gbogbo ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀ burú. 17 Torí náà, tí ẹnì kan bá mọ bí a ṣe ń ṣe ohun tó tọ́, síbẹ̀ tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni.+

5 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ sunkún, kí ẹ sì pohùn réré ẹkún torí ìbànújẹ́ tó máa bá yín.+ 2 Ọrọ̀ yín ti jẹrà, òólá* sì ti jẹ àwọn aṣọ yín.+ 3 Wúrà àti fàdákà yín ti dípẹtà, ìpẹtà wọn máa jẹ́ ẹ̀rí lòdì sí yín, ó sì máa jẹ ẹran ara yín. Ohun tí ẹ kó jọ máa dà bí iná ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.+ 4 Wò ó! Owó iṣẹ́ tí ẹ ò san fún àwọn òṣìṣẹ́ tó kórè oko yín ń ké jáde ṣáá, igbe tí àwọn olùkórè ń ké fún ìrànwọ́ sì ti dé etí Jèhófà* Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.+ 5 Ẹ ti gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ, ẹ sì ti tẹ́ ara yín lọ́rùn ní ayé. Ẹ ti bọ́ ọkàn yín yó ní ọjọ́ pípa.+ 6 Ẹ ti dáni lẹ́bi; ẹ ti pa olódodo. Ṣebí ó ń ta kò yín?

7 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ ní sùúrù, títí di ìgbà tí Olúwa máa wà níhìn-ín.+ Ẹ wò ó! Àgbẹ̀ máa ń dúró kí ilẹ̀ mú èso tó ṣeyebíye jáde, ó máa ń ní sùúrù títí òjò àkọ́rọ̀ àti òjò àrọ̀kẹ́yìn á fi rọ̀.+ 8 Kí ẹ̀yin náà ní sùúrù;+ ẹ mọ́kàn le, torí ìgbà tí Olúwa máa wà níhìn-ín ti sún mọ́lé.+

9 Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣàríwísí* ara yín, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.+ Ẹ wò ó! Onídàájọ́ ti wà lẹ́nu ilẹ̀kùn. 10 Ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kí àwọn wòlíì tó sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà*+ jẹ́ àpẹẹrẹ fún yín nínú jíjìyà ibi+ àti níní sùúrù.+ 11 Ẹ wò ó! A ka àwọn tó ní ìfaradà sí aláyọ̀.*+ Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù,+ ẹ sì ti rí ibi tí Jèhófà* jẹ́ kó yọrí sí,+ pé Jèhófà* ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an,* ó sì jẹ́ aláàánú.+

12 Ju gbogbo rẹ̀ lọ ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe búra mọ́, ì báà jẹ́ ọ̀run tàbí ayé lẹ fi búra tàbí ìbúra èyíkéyìí míì. Àmọ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́,+ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.

13 Ṣé ẹnikẹ́ni wà láàárín yín tí nǹkan nira fún? Kó má ṣe dákẹ́ àdúrà.+ Ṣé ẹnikẹ́ni wà láàárín yín tí inú rẹ̀ ń dùn? Kó máa kọ sáàmù.+ 14 Ṣé ẹnikẹ́ni ń ṣàìsàn láàárín yín? Kó pe àwọn alàgbà+ ìjọ, kí wọ́n gbàdúrà lé e lórí, kí wọ́n fi òróró pa á+ ní orúkọ Jèhófà.* 15 Àdúrà ìgbàgbọ́ sì máa mú aláìsàn náà* lára dá, Jèhófà* máa gbé e dìde. Tó bá sì ti dẹ́ṣẹ̀, a máa dárí jì í.

16 Nítorí náà, ẹ máa jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín+ fún ara yín láìfi ohunkóhun pa mọ́, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, ká lè mú yín lára dá. Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára gan-an.*+ 17 Ẹni tó máa ń mọ nǹkan lára bíi tiwa ni Èlíjà, síbẹ̀, nígbà tó gbàdúrà taratara pé kí òjò má rọ̀, òjò ò rọ̀ sórí ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà.+ 18 Ó tún gbàdúrà, òjò sì rọ̀ láti ọ̀run, ilẹ̀ wá mú èso jáde.+

19 Ẹ̀yin ará mi, tí a bá mú ẹnikẹ́ni láàárín yín ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ẹlòmíì sì yí i pa dà, 20 kí ẹ mọ̀ pé ẹni tó bá yí ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà kúrò nínú ìṣìnà+ rẹ̀ máa gbà á* lọ́wọ́ ikú, ó sì máa bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.+

Tàbí “dáni lẹ́bi.”

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “yangàn.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “mú un bí ìdẹ.”

Ní Grk., “lóyún.”

Tàbí “ẹni tí kò sí ìyípadà òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwà burúkú.”

Tàbí “gba ọkàn yín là.”

Tàbí “ojú àdánidá rẹ̀.”

Tàbí “òun gba Ọlọ́run gbọ́.”

Tàbí “kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu.”

Tàbí “Ẹ̀sìn.”

Tàbí “bá yín wí.”

Ní Grk., “òfin òmìnira.”

Ní Grk., “bá wà níhòòhò.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “èémí.”

Tàbí “le.”

Tàbí “ṣàṣìṣe.”

Ní Grk., “àgbá kẹ̀kẹ́ ìbí (orísun).”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “rákò.”

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “Omi dídùn.”

Tàbí kó jẹ́, “tí ẹ sì ń wá ipò ọlá.”

Tàbí kó jẹ́, “tí wọ́n sì ń wá ipò ọlá.”

Tàbí kó jẹ́, “ibi tí àlàáfíà bá wà, ni àwọn tó ń wá àlàáfíà máa ń gbin èso òdodo sí.”

Ní Grk., “tó ń bá ẹ̀yà ara yín.”

Tàbí “aláìṣòótọ́.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “kòkòrò.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “kùn sí; ráhùn sí.” Ní Grk., “mí ìmí ẹ̀dùn lòdì sí.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ẹni ìbùkún.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “máa ń gba tẹni rò.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí kó jẹ́, “ẹni tó ti rẹ̀ náà.”

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “máa ń ní ipa púpọ̀ tó bá wà lẹ́nu iṣẹ́.”

Tàbí “gba ọkàn rẹ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́