A7-Ẹ
Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tó Ta Yọ Tí Jésù Ṣe ní Gálílì (Apá Kẹta) àti ní Jùdíà
| ÀKÓKÒ | IBI | ÌṢẸ̀LẸ̀ | MÁTÍÙ | MÁÀKÙ | LÚÙKÙ | JÒHÁNÙ | 
|---|---|---|---|---|---|---|
| 32, lẹ́yìn Ìrékọjá | Òkun Gálílì; Bẹtisáídà | Jésù wọkọ̀ ojú omi lọ sí Bẹtisáídà, ó kìlọ̀ nípa ìwúkàrà àwọn Farisí; ó la ojú ọkùnrin afọ́jú | ||||
| Agbègbè Kesaríà ti Fílípì | Àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba Ọlọ́run; ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú àti àjíǹde rẹ̀ | |||||
| Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ní Òkè Hámónì | Ìyípadà ológo; Jèhófà sọ̀rọ̀ | |||||
| gbègbè Kesaríà ti Fílípì | Ó lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ọmọkùnrin kan | |||||
| Gálílì | Ó tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ | |||||
| Kápánáúmù | Ó fi owó tí wọ́n rí lẹ́nu ẹja san owó orí | |||||
| Ẹni tó tóbi jù nínú Ìjọba Ọlọ́run; àpèjúwe àgùntàn tó sọ nù àti ti ẹrú tí kò dárí jini | ||||||
| Gálílì sí Samáríà | Ó ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n yááfì gbogbo nǹkan torí Ìjọba Ọlọ́run | 
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Tún Ṣe ní Jùdíà
| ÀKÓKÒ | IBI | ÌṢẸ̀LẸ̀ | MÁTÍÙ | MÁÀKÙ | LÚÙKÙ | JÒHÁNÙ | 
|---|---|---|---|---|---|---|
| 32, Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn (tàbí Àtíbàbà) | Jerúsálẹ́mù | Ó kọ́ni níbi Àjọyọ̀ náà; wọ́n rán àwọn òṣìṣẹ́ pé kí wọ́n wá mú un | ||||
| Ó sọ pé “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé”; ó la ojú ọkùnrin tí wọ́n bí ní afọ́jú | ||||||
| Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ní Jùdíà | Ó rán àwọn 70 jáde; wọ́n pa dà dé tayọ̀tayọ̀ | |||||
| Jùdíà; Bẹ́tánì | Àpèjúwe ará Samáríà tó nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀; ó lọ sí ilé Màríà àti Màtá | |||||
| Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ní Jùdíà | Ó tún kọ́ wọn ní àdúrà àwòṣe; àpèjúwe ọ̀rẹ́ kan tí kò yéé bẹ̀bẹ̀ | |||||
| Ó fi ìka Ọlọ́run lé ẹ̀mí èṣù jáde; ó tún fún wọn ní àmì Jónà nìkan | ||||||
| Ó bá Farisí jẹun; ó dẹ́bi fún ìwà àgàbàgebè àwọn Farisí | ||||||
| Àwọn àpèjúwe: ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ aláìlóye àti ti ìríjú olóòótọ́ náà | ||||||
| Lọ́jọ́ Sábáàtì, ó wo obìnrin kan tí kò lè nàró sàn; àpèjúwe hóró músítádì àti ti ìwúkàrà | ||||||
| 32, Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́ | Jerúsálẹ́mù | Jerúsálẹ́mù Àpèjúwe olùṣọ́ àgùntàn àtàtà àti agbo àgùntàn; àwọn Júù fẹ́ sọ ọ́ lókùúta; ó kọjá sí Bẹ́tánì ní òdìkejì Jọ́dánì |