-
“Ó Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Ní Gbogbo Ọ̀nà Rẹ̀”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 11
“Ó Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo ní Gbogbo Ọ̀nà Rẹ̀”
1, 2. (a) Àwọn ìwà tó burú gan-an wo ni wọ́n hù sí Jósẹ́fù? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ tí wọ́n hù sí Jósẹ́fù?
ÌYÀ jẹ Jósẹ́fù gan-an láwọn àkókò tó ń dàgbà. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ni nígbà táwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ fẹ́ pa á. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n tà á fáwọn àjèjì, àwọn tó rà á wá mú un lọ sílẹ̀ òkèèrè, wọ́n sì sọ ọ́ di ẹrú. Lẹ́yìn náà, ìyàwó ọ̀gá ẹ̀ ní kó bá òun sùn. Àmọ́ Jósẹ́fù kọ̀, ni obìnrin náà bá bínú, tó sì parọ́ mọ́ Jósẹ́fù pé ó fẹ́ fipá bá òun lò pọ̀. Láìṣẹ̀ láìrò, bí Jósẹ́fù ṣe dèrò ẹ̀wọ̀n nìyẹn! Ńṣe ló dà bíi pé kò ní olùrànlọ́wọ́.
2 Àmọ́, Ọlọ́run tó “nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo” ń kíyè sí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù. (Sáàmù 33:5) Jèhófà wá gbé ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ tí wọ́n hù sí i. Ó mú kí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn náà wọ́n dá a lọ́lá, wọ́n sì gbé e ga. (Jẹ́nẹ́sísì 40:15; 41:41-43; Sáàmù 105:17, 18) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó ṣe kedere sí gbogbo èèyàn pé ńṣe ni wọ́n parọ́ mọ́ Jósẹ́fù, ó sì lo ipò ńlá tó wà láti ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 45:5-8.
Láìṣẹ̀ láìrò, wọ́n fìyà jẹ Jósẹ́fù lẹ́wọ̀n
3. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo wa la fẹ́ káwọn èèyàn máa hùwà tó dáa sí wa, tá ò sì fẹ́ káwọn èèyàn máa fi ẹ̀tọ́ wa dù wá?
3 Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o rí bí Jèhófà ṣe dá sí ọ̀rọ̀ Jósẹ́fù? Ó dájú pé ó máa tù ẹ́ nínú, torí inú wa kì í dùn tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ tàbí tá a bá rí ẹnì kan tí wọ́n rẹ́ jẹ. Ká sòótọ́, gbogbo wa la fẹ́ káwọn èèyàn máa hùwà tó dáa sí wa, kò sì sẹ́ni táá fẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀tọ́ ẹ̀ dù ú. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè fìwà jọ ọ́, ìdájọ́ òdodo sì jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Ká tó lè mọ Jèhófà dáadáa, ó yẹ ká mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí. Èyí á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan, á sì wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn.
Kí Ni Ìdájọ́ Òdodo?
4. Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí?
4 Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ohun tó máa fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ onídàájọ́ òdodo kò ju pé kẹ́ni náà máa fọwọ́ pàtàkì mú òfin, kó sì máa pa òfin mọ́ nínú bó ṣe ń hùwà sáwọn èèyàn. Ìwé kan sọ pé, “ìdájọ́ òdodo sábà máa ń kan ọ̀rọ̀ òfin, ojúṣe àwọn èèyàn, ẹ̀tọ́ wọn àti iṣẹ́ wọn, tẹ́nì kan bá sì fẹ́ ṣèdájọ́ òdodo, ó gba pé kó fìyà jẹ ẹnì kan torí ìwà burúkú tẹ́ni náà hù tàbí kó san ẹnì kan lẹ́san torí pé ẹni náà hùwà tó dáa.” Àmọ́ ìdájọ́ òdodo Jèhófà jùyẹn lọ, Jèhófà kì í wulẹ̀ ṣe ohun tó bófin mu torí ó kàn gbà pé ohun tó yẹ kóun ṣe nìyẹn.
5, 6. (a) Kí nìtumọ̀ ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti ti Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìdájọ́ òdodo”? (b) Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà?
5 Tá a bá ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti ti Gíríìkì tí wọ́n tú sí ìdájọ́ òdodo nínú Bíbélì, á jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí ìdájọ́ òdodo Jèhófà túmọ̀ sí. Ọ̀rọ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó jọra ni wọ́n lò fún ìdájọ́ òdodo nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Èyí tí wọ́n sábà máa ń tú sí “ìdájọ́ òdodo” nínú àwọn ọ̀rọ̀ náà tún lè túmọ̀ sí “ohun tó tọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:25) Wọ́n sì sábà máa ń tú ọ̀rọ̀ méjì tó kù sí “òdodo.” Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “òdodo” máa ń túmọ̀ sí pé “kéèyàn máa ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó bófin mu.” Torí náà, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ láàárín ọ̀rọ̀ náà òdodo àti ìdájọ́ òdodo.—Émọ́sì 5:24.
6 Tí Bíbélì bá wá sọ pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo, kì í sì í ṣe ojúsàájú. (Róòmù 2:11) Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Élíhù fi sọ pé: “Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú, pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!” (Jóòbù 34:10) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ò lè ṣe ohun tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu láé. Kí nìdí? Ìdí méjì pàtàkì ló mú ká gbà bẹ́ẹ̀.
7, 8. (a) Kí nìdí tí Jèhófà ò fi lè hùwà tí kò tọ́ láé? (b) Kí ló mú kí Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo tó máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo?
7 Ìdí àkọ́kọ́ ni pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́. Bá a ṣe sọ ní Orí 3 ìwé yìí, Jèhófà jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà, kò lábààwọ́n, ó sì jẹ́ olódodo. Torí náà, kò lè hùwà tí kò tọ́ láé. Ronú nípa ohun tíyẹn túmọ̀ sí ná. Torí pé Jèhófà Baba wa ọ̀run jẹ́ mímọ́, ọkàn wa balẹ̀ pé kò ní ṣe ohun tí kò dáa sáwa ọmọ rẹ̀. Bọ́rọ̀ ṣe rí lára Jésù náà nìyẹn. Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, ó gbàdúrà sí Jèhófà nípa àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀, ó ní: “Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn [àwọn ọmọ ẹ̀yìn] nítorí orúkọ rẹ.” (Jòhánù 17:11) Jèhófà nìkan ni wọ́n pè ní “Baba mímọ́” nínú Bíbélì. Èyí sì bá a mu, torí pé kò sí baba kankan tó jẹ́ èèyàn tó lè jẹ́ mímọ́ bíi ti Jèhófà. Jésù mọ̀ pé Bàbá òun mọ́ látòkè délẹ̀ láìní àbààwọ́n àti ẹ̀ṣẹ̀ kankan, torí náà ó dá Jésù lójú pé Bàbá òun máa dáàbò bo àwọn ọmọlẹ́yìn òun.—Mátíù 23:9.
8 Ìkejì, Jèhófà ò mọ tara ẹ̀ nìkan, ó sì jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ onídàájọ́ òdodo tó máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo. Àwọn tó máa ń ṣe ojúsàájú, tó sì máa ń hùwà tí kò dáa sáwọn ẹlòmíì sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí wọ́n jẹ́ olójúkòkòrò tó mọ tara wọn nìkan. Èyí sì fi hàn pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun kan nípa Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́. Ó sọ pé: “Olódodo ni Jèhófà; ó nífẹ̀ẹ́ àwọn iṣẹ́ òdodo.” (Sáàmù 11:7) Jèhófà tún sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Èmi Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Àìsáyà 61:8) Ó dájú pé ọkàn wa balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà Ọlọ́run wa máa ń dùn láti ṣe ohun tó tọ́!—Jeremáyà 9:24.
Aláàánú Ni Jèhófà, Ó sì Máa Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Lọ́nà Tó Pé
9-11. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń lo ìdájọ́ òdodo àti àánú pa pọ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé aláàánú àti onídàájọ́ òdodo lòun nínú bó ṣe ń bá àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lò?
9 Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń lo àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ lọ́nà tó tọ́, bó sì ṣe máa ń ṣe náà nìyẹn tó bá kan ìdájọ́ òdodo. Ìdí nìyẹn tí Mósè fi yin Jèhófà pé: “Àpáta náà, pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, torí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Ọlọ́run olóòótọ́, tí kì í ṣe ojúsàájú; olódodo àti adúróṣinṣin ni.” (Diutarónómì 32:3, 4) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dájọ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, kì í le koko, kì í sì í gbàgbàkugbà.
10 Ṣe ni Jèhófà máa ń lo ìdájọ́ òdodo àti àánú pa pọ̀. Sáàmù 116:5 sọ pé: “Jèhófà jẹ́ agbatẹnirò àti olódodo [tàbí “onídàájọ́ òdodo,” The New American Bible]; Ọlọ́run wa jẹ́ aláàánú.” Lóòótọ́, Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo àti aláàánú. Èyí fi hàn pé ìwà àti ìṣe méjèèjì yìí kò ta kora. Tí Jèhófà bá ń fi àánú hàn lórí ọ̀rọ̀ kan, ìyẹn ò fi hàn pé kò ní dá ẹjọ́ náà lọ́nà tó tọ́, tó bá sì fẹ́ ṣe ìdájọ́ òdodo ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó máa ṣeé lọ́nà tó le koko. Ńṣe ni Jèhófà máa ń lo àwọn ìwà àti ìṣe méjèèjì yìí pa pọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.
11 Gbogbo wa la ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, torí náà ikú tọ́ sí wa. (Róòmù 5:12) Àmọ́ inú Jèhófà kì í dùn sí ikú ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó jẹ́ ‘Ọlọ́run tó ṣe tán láti dárí jini, tó ń gba tẹni rò, tó sì jẹ́ aláàánú.’ (Nehemáyà 9:17) Síbẹ̀, torí pé ó jẹ́ mímọ́, kò lè fàyè gba àìṣòdodo. Báwo ni Jèhófà ṣe wá máa fàánú hàn sí àwa èèyàn tá a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀? Ńṣe ló fìfẹ́ pèsè ìràpadà fún wa ká lè rí ìgbàlà, ìràpadà yìí sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Bíbélì. A máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ẹ̀bùn pàtàkì yìí ní Orí 14. Ìràpadà yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti máa fàánú hàn sáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà láìsí pé ó ń ṣe ohun tó lòdì sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ tó jẹ́ pípé. Ohun tí Jèhófà ṣe yìí jẹ́rìí sí i pé ìdájọ́ òdodo rẹ̀ kò lẹ́gbẹ́, àánú rẹ̀ sì pọ̀ gan-an.—Róòmù 3:21-26.
Ìdájọ́ Òdodo Jèhófà Ń Mú Kó Wù Wá Láti Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọn
12, 13. (a) Kí nìdí tí ìdájọ́ òdodo Jèhófà fi ń mú kó wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn? (b) Kí ni Ọba Dáfídì sọ nígbà tó kíyè sí bí Jèhófà ṣe jẹ́ onídàájọ́ òdodo, báwo lèyí sì ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀?
12 Dípò tí ìdájọ́ òdodo Jèhófà á fi mú ká jìnnà sí i, ńṣe ló ń mú kó wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn. Bíbélì jẹ́ ká ri í pé Jèhófà máa ń fìfẹ́ àti àánú hàn tó bá ń ṣèdájọ́. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun jẹ́ onídàájọ́ òdodo.
13 Jèhófà máa ń ṣèdájọ́ òdodo lọ́nà tó pé, ìdí nìyẹn tó fi máa ń jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Ọba Dáfídì kíyè sí bí Jèhófà ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, títí kan òun fúnra rẹ̀, èyí mú kó mọyì ìdájọ́ òdodo Jèhófà. Torí náà, ó sọ pé: “Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, kò sì ní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀. Ìgbà gbogbo ni yóò máa ṣọ́ wọn.” (Sáàmù 37:28) Ọ̀rọ̀ yìí mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run wa ò ní kọ àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sílẹ̀ láé. Torí pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, ọkàn wa balẹ̀ pé kò ní pa wá tì láé, ó sì dá wa lójú pé á máa fìfẹ́ bójú tó wa!—Òwe 2:7, 8.
14. Báwo ni Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn aláìní jẹ ẹ́ lógún gan-an?
14 Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, ọ̀rọ̀ àwọn aláìní jẹ ẹ́ lógún gan-an. Èyí sì hàn nínú Òfin tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, Òfin yìí sọ àwọn nǹkan pàtó tó yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn ọmọ aláìníbaba àtàwọn opó. (Diutarónómì 24:17-21) Jèhófà mọ̀ pé nǹkan kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn ọmọ tí bàbá wọn ti kú àtàwọn obìnrin tí ọkọ wọn ti kú. Ìdí nìyẹn tó fi sọ ara ẹ̀ di Bàbá wọn àti ẹni tó ń dáàbò bò wọ́n, tó sì “ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún ọmọ aláìníbaba àti opó.”a (Diutarónómì 10:18; Sáàmù 68:5) Jèhófà kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ hùwà àìdáa sáwọn obìnrin àtàwọn ọmọ tí kò ní ẹni tó máa gbèjà wọn. Ó sọ pé tí wọ́n bá fìyà jẹ àwọn obìnrin yẹn àtàwọn ọmọ náà, tí wọ́n sì ké pe òun, òun máa gbọ́ igbe wọn. Ó tún sọ pé: Òun máa “bínú gidigidi.” (Ẹ́kísódù 22:22-24) Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í tètè bínú, àmọ́ inú máa ń bí i tẹ́nì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ hùwà tí kò dáa sáwọn èèyàn. Kódà, ó máa ń ká a lára gan-an tẹ́ni tí wọ́n hùwà àìdáa sí náà bá jẹ́ aláìní.—Sáàmù 103:6.
15, 16. Kí ló jẹ́ kó hàn kedere pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú?
15 Jèhófà tún sọ fún wa pé òun ‘kì í ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni, òun kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.’ (Diutarónómì 10:17) Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sáwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ tó jẹ́ pé ipò tẹ́nì kan wà tàbí bó ṣe lówó tó ló máa ń pinnu ìwà tí wọ́n máa hù sí i. Jèhófà kì í ṣojúsàájú ní tiẹ̀. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan tó fi hàn kedere pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú. Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun, ó sì fẹ́ kí wọ́n láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Dípò tí Ọlọ́run á fi fún àwọn èèyàn díẹ̀ láǹfààní yìí, ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Ìṣe 10:34, 35) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo èèyàn ni Ọlọ́run fún láǹfààní yìí, láìka ipò wọn, àwọ̀ wọn, tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé sí. Ká sòótọ́, kò sí ẹlòmíì tó jẹ́ onídàájọ́ òdodo bíi Jèhófà!
16 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà míì tí Jèhófà gbà ń ṣèdájọ́ òdodo lọ́nà tó pé, ìyẹn ni bó ṣe máa ń hùwà sáwọn tó bá ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà òdodo rẹ̀.
Jèhófà Ò Ní Ṣàìfi Ìyà Jẹ Ẹlẹ́ṣẹ̀
17. Ṣé báwọn nǹkan burúkú ṣe ń ṣẹlẹ̀ láyé yìí túmọ̀ sí pé Jèhófà kì í ṣe onídàájọ́ òdodo? Ṣàlàyé.
17 Àwọn kan lè máa rò ó pé: ‘Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni Jèhófà ò fara mọ́ àìṣòdodo, kí nìdí táwọn èèyàn fi ń hùwà ìrẹ́jẹ lónìí, tọ́pọ̀ èèyàn sì ń jìyà láìnídìí?’ Ti pé àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀ ò túmọ̀ sí pé Jèhófà kì í ṣe onídàájọ́ òdodo. Ìdí tí ìwà ìrẹ́jẹ fi pọ̀ láyé yìí ni pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn ló sì ń ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Àmọ́, ó dájú pé nǹkan máa yí pa dà láìpẹ́.—Diutarónómì 32:5.
18, 19. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ò ní gbà káwọn èèyàn mọ̀ọ́mọ̀ máa rú òfin òdodo rẹ̀ títí láé?
18 Òótọ́ ni pé Jèhófà máa ń fàánú hàn sáwọn tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti sún mọ́ ọn, síbẹ̀ kò ní gbà káwọn èèyàn máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ rẹ̀ títí láé. (Sáàmù 74:10, 22, 23) Onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, a ò sì lè tàn án jẹ, torí náà ó máa fìyà jẹ àwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin rẹ̀. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, . . . àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀.” (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, torí pé àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà rí i pé ó pọn dandan kóun fìyà jẹ àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin rẹ̀.
19 Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́. Lẹ́yìn tí Jèhófà mú wọn dé Ilẹ̀ Ìlérí, léraléra ni wọ́n ṣàìgbọràn sí i. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn ‘ba Jèhófà nínú jẹ́’ gan-an, síbẹ̀ ojú ẹsẹ̀ kọ́ ló pa wọ́n tì. (Sáàmù 78:38-41) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣàánú wọn, ó sì fún wọn láǹfààní láti yíwà pa dà. Ó sọ fún wọn pé: “Inú mi ò dùn sí ikú ẹni burúkú, bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí ìwà rẹ̀ pa dà, kó sì máa wà láàyè. Ẹ yí pa dà, ẹ yí ìwà búburú yín pa dà, ṣé ó wá yẹ kí ẹ kú ni, ilé Ísírẹ́lì?” (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Jèhófà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run, torí náà léraléra ló rán àwọn wòlíì rẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó lè fún wọn láǹfààní láti yí pa dà. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn ò fetí sí ọ̀rọ̀ Jèhófà, wọ́n sì kọ̀ láti yíwà pa dà. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Jèhófà gbà káwọn ọ̀tá ṣẹ́gun wọn kó lè gbèjà orúkọ mímọ́ rẹ̀, kó sì fi hàn pé onídàájọ́ òdodo lòun.—Nehemáyà 9:26-30.
20. (a) Kí la rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu bí Bíbélì ṣe máa ń lo kìnnìún láti ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe jẹ́ onígboyà àti onídàájọ́ òdodo?
20 Ọ̀nà tí Jèhófà gbà bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́. Ó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ń kíyè sí ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù lónìí, èyí sì máa ń bà á nínú jẹ́ gan-an. (Òwe 15:3) Ó tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa ń fàánú hàn sáwọn tó bá ronú pìwà dà. Bákan náà, a rí i pé Jèhófà máa ń mú sùúrù fáwọn èèyàn kó lè wò ó bóyá wọ́n máa yíwà pa dà. Bí Jèhófà ṣe máa ń mú sùúrù yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kò ní fìyà jẹ àwọn ẹni burúkú. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá, torí àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún jẹ́ ká rí i pé títí láé kọ́ ni Ọlọ́run á máa mú sùúrù fáwọn ẹni ibi. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣèdájọ́ òdodo, kò dà bí àwọn èèyàn tí wọ́n máa ń bẹ̀rù láti ṣe ohun tó tọ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi máa ń lo kìnnìún láti ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe jẹ́ onígboyà àti onídàájọ́ òdodo.b (Ìsíkíẹ́lì 1:10; Ìfihàn 4:7) Èyí jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa mú ìwà ìrẹ́jẹ kúrò láyé. Torí náà, a lè ṣàkópọ̀ ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣèdájọ́ báyìí pé: ó mọ ìgbà tó yẹ kóun fìyà jẹ ẹni tó bá ṣẹ̀, ó sì mọ ìgbà tó yẹ kóun fàánú hàn.—2 Pétérù 3:9.
Sún Mọ́ Ọlọ́run Tó Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo
21. Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ṣèdájọ́ òdodo, irú ẹni wo ló yẹ ká gbà pé ó jẹ́, kí sì nìdí?
21 Tá a bá ń ronú nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣèdájọ́ òdodo, kò yẹ ká máa rò pé Jèhófà kàn jẹ́ adájọ́ tí kò láàánú tó ń wá àwọn tó máa fìyà jẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká rí Jèhófà bíi Baba tí kì í gbàgbàkugbà, àmọ́ tó ń fìfẹ́ bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀ káyé wọn lè dáa. Torí pé onídàájọ́ òdodo ni Baba wa ọ̀run Jèhófà, ìgbà gbogbo ló máa ń ṣe ohun tó tọ́, ó sì máa ń fàánú hàn sáwa ọmọ rẹ̀ tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì wá.—Sáàmù 103:10, 13.
22. Ìrètí wo ni ìdájọ́ òdodo Jèhófà mú ká ní, kí sì nìdí tó fi fún wa ní ìrètí yìí?
22 Inú wa dùn gan-an bá a ṣe mọ̀ pé ìdájọ́ òdodo Jèhófà kọjá pé kó kàn máa fìyà jẹ àwọn aṣebi. Ìdájọ́ òdodo Jèhófà ló mú ká ní ìrètí àgbàyanu pé a máa wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun “níbi tí òdodo á máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Ìdí tó sì fi fún wa ní ìrètí yìí ni pé ńṣe ni ìdájọ́ òdodo rẹ̀ máa ń mú kó wá bó ṣe máa gbani là dípò táá fi máa wá bó ṣe máa fìyà jẹni. Ká sòótọ́, ìdájọ́ òdodo ṣe pàtàkì gan-an lára àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà, tá a bá sì lóye bí Jèhófà ṣe ń lò ó, ó máa wù wá pé ká túbọ̀ sún mọ́ ọn! Nínú àwọn orí tó tẹ̀ lé e, a máa túbọ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣèdájọ́ òdodo.
a Ọ̀rọ̀ náà “ọmọ aláìníbaba” jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe àwọn ọmọkùnrin tí kò ní baba nìkan ni Jèhófà ń bójú tó, ó tún máa ń bójú tó àwọn ọmọbìnrin tí kò ní baba. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe dá sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì lẹ́yìn tí bàbá wọn kú láìní ọmọkùnrin. Ńṣe ni Jèhófà ní kí wọ́n fún àwọn ọmọbìnrin náà ní ogún bàbá wọn. Jèhófà wá ní kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí di òfin ní Ísírẹ́lì káwọn èèyàn má bàa máa fi ẹ̀tọ́ àwọn ọmọbìnrin aláìníbaba dù wọ́n.—Nọ́ńbà 27:1-8.
b Ó jọni lójú pé nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa ṣèdájọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ Jèhófà fi ara ẹ̀ wé kìnnìún.—Jeremáyà 25:38; Hósíà 5:14.
-
-
“Ṣé Ọlọ́run Jẹ́ Aláìṣòdodo Ni?”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 12
“Ṣé Ọlọ́run Jẹ́ Aláìṣòdodo Ni?”
1. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí wọ́n bá rẹ́ ẹnì kan jẹ?
ÀWỌN gbájú-ẹ̀ gba gbogbo owó tí arúgbó kan tó jẹ́ opó ti kó jọ láti máa fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Ọ̀dájú abiyamọ kan gbọ́mọ ẹ̀ jòjòló jù síbì kan ó sì sá lọ. Wọ́n ju ọkùnrin kan sẹ́wọ̀n torí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò mọ ohunkóhun nípa ẹ̀. Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tó o bá gbọ́ irú àwọn nǹkan yìí? Ó dájú pé inú máa ń bí wa, ó sì máa ń ká wa lára gan-an tá a bá gbọ́ nípa irú àwọn ìwà burúkú bẹ́ẹ̀. Kódà, tí wọ́n bá rẹ́ ẹnì kan jẹ, a máa ń fẹ́ kí wọ́n ran ẹni náà lọ́wọ́, kẹ́ni tó rẹ́ni jẹ sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Tí kò bá wá rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè mú ká máa béèrè pé: ‘Ṣé Ọlọ́run tiẹ̀ ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé? Kí nìdí tí kò fi wá nǹkan ṣe sí i?’
2. Báwo ni ìwà ìrẹ́jẹ tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ṣe rí lára Hábákúkù, kí sì nìdí tí Jèhófà kò fi bá a wí nítorí ohun tó sọ?
2 Ọjọ́ pẹ́ táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti máa ń béèrè irú àwọn ìbéèrè yìí. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Hábákúkù gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Kí nìdí tí o fi ń jẹ́ kí ohun búburú ṣẹlẹ̀ níṣojú mi? Kí sì nìdí tí o fi fàyè gba ìnilára? Kí nìdí tí ìparun àti ìwà ipá fi ń ṣẹlẹ̀ níṣojú mi? Kí sì nìdí tí ìjà àti aáwọ̀ fi wà káàkiri?” (Hábákúkù 1:3) Àwọn ìbéèrè tí Hábákúkù béèrè yìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ yẹn ká a lára gan-an, Jèhófà ò sì bá a wí rárá, torí pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló dá wa lọ́nà tá a fi lè kórìíra ìrẹ́jẹ. Bá ò tiẹ̀ lè ṣe bíi ti Jèhófà lọ́nà tó pé, a lè fìwà jọ ọ́ torí pé ó dá wa láwòrán ara ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń wù wá kí nǹkan lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
Jèhófà Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ
3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà ń rí ìwà ìrẹ́jẹ tó ń lọ láyé jù wá lọ?
3 Kò sí ohun tó pa mọ́ lójú Ọlọ́run, torí náà ó ń kíyè sí báwọn èèyàn ṣe ń hùwà ìrẹ́jẹ lónìí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà ayé Nóà, ó sọ pé: “Jèhófà wá rí i pé ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an ní ayé, ó sì rí i pé kìkì ohun búburú ló ń rò lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:5) Jẹ́ ká wo ohun tí gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tá a mọ̀ nípa ìwà ìrẹ́jẹ kò ju ohun tá a gbọ́ tàbí tó ṣẹlẹ̀ sáwa fúnra wa. Àmọ́ ní ti Jèhófà, ó ń rí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù kárí ayé. Gbogbo ẹ̀ ló ń rí! Yàtọ̀ síyẹn, ó mọ gbogbo èrò burúkú tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, tó ń mú kí wọ́n máa rẹ àwọn ẹlòmíì jẹ.—Jeremáyà 17:10.
4, 5. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n ń rẹ́ jẹ ṣe pàtàkì sí Jèhófà? (b) Báwo ni wọ́n ṣe hùwà àìdáa sí Jèhófà fúnra ẹ̀?
4 Àmọ́, kì í ṣe pé Jèhófà kàn dákẹ́ tó ń wo gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ tó ń lọ láyé o. Ó ń kíyè sí àwọn tí wọ́n rẹ́ jẹ, ó sì máa ń káàánú wọn. Nígbà táwọn ọ̀tá ń ni àwọn èèyàn Jèhófà lára, àánú wọn ṣe é “torí pé àwọn tó ń ni wọ́n lára àtàwọn tó ń fìyà jẹ wọ́n mú kí wọ́n máa kérora.” (Àwọn Onídàájọ́ 2:18) Ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé táwọn èèyàn bá ń rí ìwà ìrẹ́jẹ lemọ́lemọ́, tó bá yá kò ní fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ nǹkan kan mọ́ lójú wọn, àwọn náà sì lè wá di ọ̀dájú. Àmọ́, ti Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀! Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ọdún tó ti ń rí oríṣiríṣi ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń rẹ́ni jẹ, síbẹ̀ ó ṣì kórìíra ìrẹ́jẹ. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run kórìíra àwọn ìwà bí “ahọ́n èké,” “ọwọ́ tó ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,” àti “ẹlẹ́rìí èké tí kò lè ṣe kó má parọ́.”—Òwe 6:16-19.
5 Jẹ́ ká wo ẹ̀rí míì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kórìíra kí wọ́n máa rẹ́ èèyàn jẹ lóòótọ́. Nígbà tó kíyè sí báwọn aṣáájú ní Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, ó bá wọn wí lọ́nà tó le gan-an. Jèhófà rán wòlíì Míkà sí wọn, ó ní kó bi wọ́n pé: “Ṣé kò yẹ kí ẹ mọ ohun tó tọ́?” Lẹ́yìn tí Jèhófà ṣàpèjúwe báwọn ọkùnrin oníwà ìbàjẹ́ yẹn ṣe ń ṣi agbára lò, ó wá sọ ohun tó máa gbẹ̀yìn wọn, ó ní: “Wọ́n á ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, àmọ́ kò ní dá wọn lóhùn. Ó máa fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wọn ní àkókò yẹn, torí ìwà burúkú wọn.” (Míkà 3:1-4) Ẹ ò rí i bí Jèhófà ṣe kórìíra ìrẹ́jẹ tó! Kódà, òun fúnra ẹ̀ mọ bó ṣe máa ń rí, torí pé wọ́n ti hùwà àìdáa sóun náà rí! Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń pẹ̀gàn ẹ̀. (Òwe 27:11) Bákan náà, àwọn èèyàn ṣe ohun tó dun Jèhófà gan-an nígbà tí wọ́n fìyà jẹ Ọmọ ẹ̀, tí wọ́n sì pa á bí wọ́n ṣe ń pa ọ̀daràn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (1 Pétérù 2:22; Àìsáyà 53:9) Ó dá wa lójú pé Jèhófà ń rí gbogbo ìyà tó ń jẹ àwọn tí wọ́n ń rẹ́ jẹ, ó sì dájú pé ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́.
6. Báwo ló ṣe sábà máa ń rí lára wa tí wọ́n bá rẹ́ àwa tàbí àwọn míì jẹ, kí sì nìdí tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀?
6 Lóòótọ́, a mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ìrẹ́jẹ àti pé ó máa ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀, àmọ́ ó ṣì máa ń ká wa lára táwọn èèyàn bá rẹ́ wa jẹ tàbí tá a bá gbọ́ pé wọ́n rẹ́ ẹnì kan jẹ. Ìyẹn ò burú rárá, torí pé ńṣe ni Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara ẹ̀, ìwà ìrẹ́jẹ sì lòdì sírú ẹni tí Jèhófà jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Kí wá nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ìrẹ́jẹ?
Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Kan
7. Báwo ni Sátánì ṣe ba Jèhófà lórúkọ jẹ́ tó sì ta ko ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso?
7 Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun pàtàkì kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. Bá a ṣe mọ̀, Ẹlẹ́dàá wa ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé yìí àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀. (Sáàmù 24:1; Ìfihàn 4:11) Àmọ́, kò pẹ́ sígbà tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ lẹnì kan ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, tó sì tún sọ pé Ọlọ́run ò lè ṣàkóso wọn lọ́nà tó dáa. Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀? Jèhófà pàṣẹ fún Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, pé kò gbọ́dọ̀ jẹ èso ọ̀kan lára àwọn igi tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ ẹ́? Ọlọ́run sọ fún un pé: ‘Ó dájú pé o máa kú.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún Ádámù àti Éfà aya rẹ̀ kò ṣòro rárá. Àmọ́, Sátánì sọ fún Éfà pé ńṣe ni Ọlọ́run ò fẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tó wù wọ́n. Kí ni Sátánì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ tí Éfà bá jẹ lára èso yẹn? Sátánì sọ fún un pé: “Ó dájú pé ẹ ò ní kú. Torí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ tí ẹ bá jẹ ẹ́ ni ojú yín máa là, ẹ máa dà bí Ọlọ́run, ẹ sì máa mọ rere àti búburú.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.
8. (a) Kí ni Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ fún Éfà nípa Jèhófà? (b) Kí ni Sátánì sọ nípa ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso?
8 Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ fún Éfà ni pé ńṣe ni Jèhófà ń parọ́ fún un, tí kò sì jẹ́ kó mọ àwọn nǹkan pàtàkì tó yẹ kó mọ̀. Ó fẹ́ kí Éfà máa rí Jèhófà bí ẹni burúkú. Bí Sátánì ṣe kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run nìyẹn, tó sì tún ta ko ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso. Òótọ́ kan ni pé Sátánì ò sọ pé Jèhófà ò láṣẹ lórí gbogbo ohun tó dá. Àmọ́, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé ipò yẹn ò tọ́ sí Ọlọ́run. Ó tún sọ pé ọ̀nà tó dáa kọ́ ni Ọlọ́run gbà ń lo àṣẹ tó ní àti pé ìṣàkóso rẹ̀ ò lè ṣeni láǹfààní.
9. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ló sì jẹ yọ? (b) Kí nìdí tí Jèhófà ò fi pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀?
9 Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, wọ́n jẹ lára èso igi tí Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ. Ọlọ́run ti sọ pé wọ́n máa kú tí wọ́n bá jẹ ẹ́, torí náà wọ́n kú. Ẹ ò rí i pé irọ́ ni Sátánì pa fún wọn! Àmọ́, ohun tí Sátánì sọ mú kí àwọn ìbéèrè pàtàkì kan jẹ yọ. Ṣé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso àwa èèyàn lóòótọ́, àbí èèyàn ló yẹ kó máa ṣàkóso ara ẹ̀? Ṣé Jèhófà ń ṣàkóso bó ṣe yẹ lóòótọ́? Jèhófà lágbára láti pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́, ẹ rántí pé Sátánì ò sọ pé Ọlọ́run ò lágbára, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, tó sì sọ pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso. Torí náà, ká sọ pé Jèhófà ti pa Ádámù, Éfà àti Sátánì run lójú ẹsẹ̀, Jèhófà ì bá má fi hàn pé alákòóso tó dáa lòun. Ńṣe ló kàn máa dà bíi pé òótọ́ lohun tí Sátánì sọ. Ọ̀nà kan ṣoṣo táwọn èèyàn fi lè mọ̀ bóyá wọ́n máa lè ṣàkóso ara wọn láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ni pé kí Ọlọ́run fún wọn láyè kí wọ́n gbìyànjú ẹ̀ wò.
10. Kí ni ìtàn jẹ́ ká mọ̀ nípa ìṣàkóso èèyàn?
10 Kí làwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn jẹ́ ká mọ̀ nípa ìjọba èèyàn? Oríṣiríṣi ìjọba làwọn èèyàn ti dán wò, irú bí ìjọba apàṣẹwàá, ìjọba tiwa-n-tiwa, ìjọba àjùmọ̀ní àti ìjọba Kọ́múníìsì. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ ni gbogbo rẹ̀ pa dà ń já sí, ó ní: “Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Àbájọ tí wòlíì Jeremáyà fi sọ pé: “Jèhófà, mo mọ̀ dáadáa pé ọ̀nà èèyàn kì í ṣe tirẹ̀. Àní kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
11. Kí nìdí tí Jèhófà fi gbà káwọn èèyàn ṣàkóso ara wọn?
11 Jèhófà mọ̀ látìbẹ̀rẹ̀ pé ìyà máa jẹ àwa èèyàn gan-an tá a bá ń ṣàkóso ara wa láìsí ìrànlọ́wọ́ òun. Ṣé a lè wá sọ pé ìkà ni Ọlọ́run bó ṣe gbà káwọn èèyàn ṣàkóso ara wọn? Rárá o! Jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Ká sọ pé o lọ́mọ kan tó ń ṣàìsàn tó lè gbẹ̀mí ẹ̀, táwọn dókítà sì sọ pé ó dìgbà tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ abẹ fún un kí ara ẹ̀ tó lè yá. O mọ̀ pé iṣẹ́ abẹ yìí máa fa ìrora fún ọmọ rẹ, ìyẹn sì bà ẹ́ nínú jẹ́ gidigidi. Síbẹ̀, o mọ̀ pé iṣẹ́ abẹ yẹn á jẹ́ kí ọmọ rẹ ní ìlera tó dáa sí i lọ́jọ́ iwájú. Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run mọ̀, ó sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé bóun ṣe gbà káwọn èèyàn ṣàkóso ara wọn máa jẹ́ kí wàhálà dé bá wọn, á sì mú kí ìyà jẹ wọ́n. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16-19) Àmọ́, Ọlọ́run tún mọ̀ pé ohun kan ṣoṣo tó lè mú kí ìtura dé bá àwọn èèyàn ni pé kóun jẹ́ kí wọ́n fojú ara wọn rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn tí wọ́n bá ń ṣàkóso ara wọn láìsí ìrànlọ́wọ́ òun. Ìyẹn á wá yanjú bí Sátánì ṣe ta ko ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso, ọ̀rọ̀ náà ò sì ní gbérí mọ́ láé.
Kí Nìdí Táwa Èèyàn Fi Ń Sin Ọlọ́run?
12. Bá a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ Jóòbù, ẹ̀sùn wo ni Sátánì fi kan gbogbo àwa èèyàn?
12 Kì í ṣe pé Sátánì ta ko Jèhófà pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso àwa èèyàn nìkan, àmọ́ ó tún ba àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lórúkọ jẹ́ torí ó sọ pé a ò lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Sátánì sọ fún Jèhófà nípa ọkùnrin olódodo tó ń jẹ́ Jóòbù, Sátánì sọ pé: “Ṣebí o ti ṣe ọgbà yí i ká láti dáàbò bo òun, ilé rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní? O ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sì ti pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ náà. Àmọ́, kí nǹkan lè yí pa dà, na ọwọ́ rẹ, kí o sì kọ lu gbogbo ohun tó ní, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.”—Jóòbù 1:10, 11.
13. Kí ni Sátánì dọ́gbọ́n sọ nígbà tó fẹ̀sùn kan Jóòbù, báwo lọ̀rọ̀ náà sì ṣe kan gbogbo èèyàn?
13 Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé torí pé Jèhófà ń dáàbò bo Jóòbù ló ṣe ń sin Jèhófà. Ohun tọ́rọ̀ Sátánì yẹn túmọ̀ sí ni pé ẹ̀tàn ni gbogbo bí Jóòbù ṣe ń sọ pé òun ń pa ìwà títọ́ mọ́ àti pé torí ohun tí Jóòbù máa rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló ṣe ń sìn ín. Sátánì sọ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé èèyàn dáadáa ni Jóòbù, tí Ọlọ́run ò bá bù kún un mọ́, ó máa bú Ọlọ́run. Sátánì mọ̀ pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jóòbù jẹ́, ó rí i pé “olódodo àti olóòótọ́ èèyàn ni, ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú.”a Àmọ́, Sátánì gbà pé tóun bá lè mú kí Jóòbù fi Jèhófà sílẹ̀, ó dájú pé òun á lè ṣe ohun kan náà fáwọn èèyàn tó kù. Sátánì wá tipa bẹ́ẹ̀ fẹ̀sùn kan gbogbo èèyàn lápapọ̀ pé torí ohun tí wọ́n máa rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ni wọ́n ṣe ń sìn ín. Èyí sì túbọ̀ ṣe kedere nínú ohun tí Sátánì sọ fún Jèhófà lẹ́yìn ìyẹn, ó ní: “Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀.”—Jóòbù 1:8; 2:4.
14. Kí ló fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan àwa èèyàn?
14 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ṣe ohun tó fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa. Bíi ti Jóòbù, àwọn náà jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà lójú àdánwò. Ohun tí wọ́n ṣe yìí múnú Jèhófà dùn, ó sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti fún Sátánì lésì lórí ohun tó sọ pé tí ìṣòro bá dé bá àwa èèyàn a ò ní sin Ọlọ́run mọ́. (Hébérù 11:4-38) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run, tí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i jálẹ̀ ayé wọn. Kódà, láwọn àkókò tí nǹkan le koko fún wọn, ńṣe ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, torí wọ́n mọ̀ pé ó máa fún wọn lókun, á sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fara da ìṣòro wọn.—2 Kọ́ríńtì 4:7-10.
15. Kí la lè béèrè nípa àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run ti ṣe sẹ́yìn àti èyí tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?
15 Nígbà tí Sátánì ta ko Jèhófà pé ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso ò dáa, tó tún fẹ̀sùn kan àwa èèyàn pé a ò sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, bí Jèhófà ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ká rí i pé onídàájọ́ òdodo ni lóòótọ́. Àmọ́, Jèhófà tún ṣe àwọn nǹkan míì tó jẹ́ ká rí i pé ó jẹ́ onídàájọ́ òdodo. Bíbélì jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ṣèdájọ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àtohun tó ṣe lórí ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè kan. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà ti ń ṣèdájọ́ òdodo àti pé ó máa ṣèdájọ́ òdodo nígbà tó bá ń dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ lọ́jọ́ iwájú?
Ìdájọ́ Ọlọ́run Ló Dáa Jù Lọ
Ó dájú pé Jèhófà kò ní “pa olódodo run pẹ̀lú ẹni burúkú”
16, 17. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé àìpé kì í jẹ́ káwa èèyàn ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́?
16 Bíbélì sọ pé Jèhófà “ń ṣe ìdájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.” (Diutarónómì 32:4) Òótọ́ sì lọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ a ò lè sọ bẹ́ẹ̀ nípa àwa èèyàn, ó ṣe tán àìpé wa kì í jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn nǹkan, ìyẹn sì máa ń jẹ́ ká dájọ́ lọ́nà tí kò tọ́ lọ́pọ̀ ìgbà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ábúráhámù. Nígbà tí Jèhófà sọ pé òun máa pa ìlú Sódómù run torí ìwà burúkú táwọn èèyàn ibẹ̀ ń hù, ńṣe ni Ábúráhámù bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jèhófà pé kó má ṣe bẹ́ẹ̀. Ó wá bi Jèhófà pé: “Ṣé o máa pa olódodo run pẹ̀lú ẹni burúkú ni?” (Jẹ́nẹ́sísì 18:23-33) Ó dájú pé Jèhófà ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Torí ìgbà tí Lọ́ọ̀tì olódodo àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ dé ìlú Sóárì láìséwu ni Jèhófà tó “rọ òjò imí ọjọ́ àti iná lé Sódómù” lórí. (Jẹ́nẹ́sísì 19:22-24) Ní ti Jónà, lẹ́yìn tó kéde pé Ọlọ́run máa pa ìlú Nínéfè run, ńṣe ló ń retí pé kí Jèhófà pa wọ́n run. Àmọ́, àwọn èèyàn náà ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Ọlọ́run sì fàánú hàn sí wọn. Nígbà tí Jónà wá rí i pé Ọlọ́run ò pa wọ́n run mọ́, ‘inú bí i gan-an.’—Jónà 3:10–4:1.
17 Ohun tí Jèhófà ṣe fún Lọ́ọ̀tì jẹ́ kó túbọ̀ dá Ábúráhámù lójú pé torí pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ó máa dá àwọn olódodo sí tó bá fẹ́ pa àwọn aláìṣòdodo run. Àmọ́, ní ti Jónà ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ará ìlú Nínéfè ló jẹ́ kó túbọ̀ yé e pé àánú Jèhófà pọ̀ gan-an. Jónà wá rí i pé táwọn èèyàn burúkú bá yí ọ̀nà wọn pa dà, Jèhófà ‘ṣe tán láti dárí jì wọ́n.’ (Sáàmù 86:5) Jèhófà ò dà bí àwọn èèyàn, tí wọ́n máa ń fìyà jẹni kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn lágbára, tí wọ́n sì máa ń bẹ̀rù láti fàánú hàn torí káwọn èèyàn máa bàa rò pé ojo ni wọ́n. Ní ti Jèhófà, ó máa ń fàánú hàn ní gbogbo ìgbà tó bá yẹ.—Àìsáyà 55:7; Ìsíkíẹ́lì 18:23.
18. Sọ àpẹẹrẹ kan látinú Bíbélì tó jẹ́ ká rí i pé ohun téèyàn bá ṣe ni Jèhófà máa fi dá a lẹ́jọ́.
18 Òótọ́ ni pé Jèhófà máa ń fàánú hàn nígbà tó bá ń ṣèdájọ́, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó máa ń gbójú fo ìwà burúkú tẹ́nì kan bá hù. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi Jèhófà sílẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà, Jèhófà sọ fún wọn pé: “Màá fi iṣẹ́ ọwọ́ yín dá yín lẹ́jọ́, màá sì pè yín wá jíhìn torí gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe. Mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín, torí màá fi ìwà yín san yín lẹ́san.” (Ìsíkíẹ́lì 7:3, 4) Nítorí náà, táwọn èèyàn bá kọ̀ láti jáwọ́ nínú ìwà burúkú, Jèhófà á dá wọn lẹ́jọ́. Kò sì ní dáni lẹ́jọ́ láìsí ẹ̀rí tó dájú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà gbọ́ igbe àwọn èèyàn nípa Sódómù àti Gòmórà, ó sọ pé: “Èmi yóò lọ wò ó bóyá ohun tí mò ń gbọ́ nípa wọn náà ni wọ́n ń ṣe.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ò dà bí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n máa ń fi ìkánjú dáni lẹ́jọ́ láìmọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an! Òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé “Ọlọ́run olóòótọ́, tí kì í ṣe ojúsàájú” ni.—Diutarónómì 32:4.
Jẹ́ Kó Dá Ẹ Lójú Pé Ìgbà Gbogbo Ni Jèhófà Máa Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo
19. Kí la lè ṣe tá ò bá mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣe àwọn nǹkan kan?
19 Bíbélì ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ìdí tí Jèhófà fi dá àwọn kan lẹ́jọ́ nígbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan àti àwùjọ èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, tá a bá ka ìtàn tàbí àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú Bíbélì tí kò yé wa, tí Bíbélì ò sì ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ẹ̀, ṣe ló yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti wòlíì Míkà tó sọ pé: “Màá dúró de Ọlọ́run ìgbàlà mi.”—Míkà 7:7.
20, 21. Kí ló mú kó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́?
20 Ohun tó dá wa lójú ni pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́. Táwọn kan bá tiẹ̀ ń gbójú fo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù, Jèhófà ṣèlérí pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san.” (Róòmù 12:19) Tá a bá ṣe sùúrù, tá a sì fọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́, ńṣe làwa náà ń fi hàn pé a fọkàn tán Jèhófà bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Ṣé Ọlọ́run jẹ́ aláìṣòdodo ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá!”—Róòmù 9:14.
21 ‘Àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ là ń gbé yìí. (2 Tímótì 3:1) Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ìyà ń jẹ torí pé ìwà ìrẹ́jẹ àti “ìwà ìnilára” pọ̀ láyé. (Oníwàásù 4:1) Àmọ́ Jèhófà ò yí pa dà, ó ṣì kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ. Kódà, àánú àwọn tí wọ́n rẹ́ jẹ máa ń ṣe é, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, tá a sì fara mọ́ ọn pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ, ó máa fún wa lókun ká lè máa fara dà á títí dìgbà tó máa fòpin sí gbogbo ìrẹ́jẹ lábẹ́ Ìjọba rẹ̀.—1 Pétérù 5:6, 7.
a Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa Jóòbù, ó sọ pé: “Kò sí ẹni tó dà bí rẹ̀ ní ayé.” (Jóòbù 1:8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀yìn ìgbà tí Jósẹ́fù kú ni Jóòbù gbé ayé, ó sì jọ pé Ọlọ́run ò tíì yan Mósè ṣe aṣáájú Ísírẹ́lì nígbà yẹn. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé kò sí ẹnì kankan láyé nígbà yẹn tó jẹ́ olóòótọ́ bíi ti Jóòbù.
-
-
“Òfin Jèhófà Pé”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 13
“Òfin Jèhófà Pé”
1, 2. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í fọwọ́ pàtàkì mú òfin, àmọ́ èrò wo la máa ní nípa àwọn òfin Jèhófà tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn?
LÓNÌÍ, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè làwọn èèyàn ò ti fọwọ́ pàtàkì mú òfin. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé, òfin ṣòroó lóye. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó ń ṣàkóso kì í ṣe ohun tó tọ́, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ìyà jẹ àwọn èèyàn. Táwọn èèyàn bá tún gbé ọ̀rọ̀ kan lọ sílé ẹjọ́ kí wọ́n lè jà fẹ́tọ̀ọ́ wọn, owó ńlá ni wọ́n máa ná, ńṣe làwọn adájọ́ á sì máa fòní dónìí, fọ̀la dọ́la.
2 Àmọ́ onísáàmù kan sọ ọ̀rọ̀ kan ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún méje (2,700) ọdún sẹ́yìn. Ohun tó sọ yàtọ̀ pátápátá sí èrò àwọn èèyàn nípa òfin bá a ṣe rí i nínú ìpínrọ̀ tó ṣáájú. Ó sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!” (Sáàmù 119:97) Kí nìdí tí òfin yìí fi wu onísáàmù náà? Ìdí ni pé ọ̀dọ́ Jèhófà Ọlọ́run ni òfin náà ti wá, kì í ṣe ti ìjọba èèyàn. Bí ìwọ náà bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn òfin Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ̀ bíi ti onísáàmù yìí. Èyí á sì jẹ́ kó o túbọ̀ lóye bí Jèhófà tó jẹ́ onídàájọ́ tó ga jù lọ láyé àtọ̀run ṣe ń ronú.
Afúnnilófin Tó Ga Jù Lọ
3, 4. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi hàn pé òun jẹ́ Afúnnilófin?
3 Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kan ṣoṣo ni Afúnnilófin àti Onídàájọ́.” (Jémíìsì 4:12) Ká sòótọ́, Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Afúnnilófin tòótọ́. Kódà, òfin tó gbé kalẹ̀ ló fi ‘ń darí àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run.’ (Jóòbù 38:33) Jèhófà tún ní òfin tó ń darí àìmọye àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ mímọ́ bí wọ́n ṣe ń sìn ín, ìdí nìyẹn tí gbogbo wọn fi ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ níṣọ̀kan, bí ipò wọn tiẹ̀ yàtọ̀ síra.—Sáàmù 104:4; Hébérù 1:7, 14.
4 Bákan náà, Jèhófà fún àwa èèyàn lófin. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ní ẹ̀rí ọkàn tó dà bí òfin tó ń ṣiṣẹ́ nínú wa, tó sì ń tọ́ wa sọ́nà ká lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Róòmù 2:14) Torí pé ẹni pípé ni Ádámù àti Éfà, ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé òfin díẹ̀ ni Ọlọ́run fún wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17) Àmọ́ aláìpé làwa, torí náà a nílò òfin tó pọ̀ ká lè máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Jèhófà jẹ́ káwọn olórí ìdílé bíi Nóà, Ábúráhámù àti Jékọ́bù mọ àwọn òfin òun, wọ́n sì ṣàlàyé àwọn òfin náà fáwọn ìdílé wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 6:22; 9:3-6; 18:19; 26:4, 5) Jèhófà di Afúnnilófin lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nígbà tó lo Mósè láti fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní àkópọ̀ òfin kan tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Òfin Mósè. Àkópọ̀ òfin yìí jẹ́ ká mọ púpọ̀ sí i nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo ìdájọ́ òdodo.
Díẹ̀ Lára Àwọn Òfin Mósè
5. Ṣé òfin tó pọ̀, téèyàn ò lè tètè lóye, tí kò sì rọrùn láti pa mọ́ ni Òfin Mósè, kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
5 Ọ̀pọ̀ èèyàn lè máa rò pé Òfin Mósè ti pọ̀ jù, èèyàn ò lè tètè lóye ẹ̀, kò sì rọrùn láti pa mọ́. Irú èrò bẹ́ẹ̀ kò tọ̀nà rárá. Lóòótọ́, àpapọ̀ òfin náà ju ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) lọ, ìyẹn sì lè mú kó dà bíi pé ó pọ̀. Àmọ́, rò ó wò ná: Nígbà tó fi máa di oṣù January ọdún 1990, òfin tí ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nìkan ní kún ìwé òfin tó jẹ́ ìdìpọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), ojú ìwé rẹ̀ lápapọ̀ sì ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́jọ (160,000) lọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, láàárín ọdún 1990 sí September 1999 wọ́n ti fi òfin tó tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti ogójì (540) kún un! Torí náà, tá a bá fi Òfin Mósè wé òfin táwọn èèyàn ń gbé kalẹ̀, a máa rí i pé Òfin Mósè ò pọ̀ rárá. Síbẹ̀, Òfin yìí jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ohun tí wọ́n máa ṣe láwọn ipò kan tó jẹ́ pé òfin táwọn èèyàn ṣe ò tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ rárá. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn Òfin Mósè.
6, 7. (a) Kí ló mú kí Òfin Mósè yàtọ̀ sí òfin táwọn èèyàn ṣe, èwo ló sì ṣe pàtàkì jù nínú Òfin náà? (b) Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lè fi hàn pé àwọn fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà?
6 Òfin Mósè jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ. Èyí mú kí Òfin Mósè yàtọ̀ pátápátá sí òfin táwọn èèyàn ṣe. Èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú òfin náà lèyí tó sọ pé: “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni. Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun? Ó fẹ́ kí wọ́n máa sin òun, kí wọ́n sì fara mọ́ ọn pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso wọn.—Diutarónómì 6:4, 5; 11:13.
7 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi hàn pé àwọn fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà tí wọ́n bá ń tẹrí ba fáwọn tí Jèhófà yàn pé kó máa bójú tó wọn. Ìyẹn àwọn òbí, àwọn ìjòyè, àwọn onídàájọ́, àwọn àlùfáà, àtàwọn ọba nígbà tó yá. Jèhófà sọ pé òun gangan lẹni tó bá ṣọ̀tẹ̀ sáwọn èèyàn yìí ń ṣọ̀tẹ̀ sí. Àmọ́, àwọn tó wà nípò àṣẹ náà ò gbọ́dọ̀ ṣi agbára wọn lò, Jèhófà sọ pé tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun máa fìyà jẹ wọ́n. (Ẹ́kísódù 20:12; 22:28; Diutarónómì 1:16, 17; 17:8-20; 19:16, 17) Torí náà, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí kan àwọn tí Jèhófà ní kó máa bójú tó wọn ló gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà.
8. Báwo ni Òfin Mósè ṣe jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ bí wọ́n ṣe lè wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run?
8 Òfin Mósè jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ bí wọ́n ṣe lè wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “mímọ́” àti “ìjẹ́mímọ́” fara hàn ní ìgbà tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó dín ogún (280) nínú Òfin Mósè. Òfin Mósè jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun mímọ́ àti ohun tí kò mọ́, ó jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan bí àádọ́rin (70) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó lè sọ ẹnì kan di aláìmọ́, tí kò fi ní láǹfààní láti jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù. Àwọn òfin yìí sọ nípa ìmọ́tótó ara àti àyíká, ọ̀rọ̀ nípa oúnjẹ, títí kan bí wọ́n ṣe lè máa bo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀. Àwọn òfin yẹn dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì mú kí ìlera wọn dáa gan-an.a Àmọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún máa rí àǹfààní tó jùyẹn lọ tí wọ́n bá ń pa Òfin yẹn mọ́, á jẹ́ kí wọ́n rí ojúure Jèhófà, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n máa hùwà ìbàjẹ́ bíi tàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.
9, 10. Òfin wo ni Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí, àǹfààní wo lòfin náà sì ṣe wọ́n?
9 Òfin Mósè sọ pé àwọn tó bá ní ìbálòpọ̀ máa jẹ́ aláìmọ́ láàárín àkókò kan, kódà tó bá jẹ́ pé tọkọtaya làwọn méjèèjì. Òfin náà tún sọ pé obìnrin tó bímọ máa jẹ́ aláìmọ́ láàárín àkókò kan. (Léfítíkù 12:2-4; 15:16-18) Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé ẹ̀ṣẹ̀ ni kí tọkọtaya ní ìbálòpọ̀ tàbí kí wọ́n bímọ, ó ṣe tán ẹ̀bùn pàtàkì látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:18-25) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní Òfin yìí kí wọ́n lè máa jẹ́ mímọ́, kí wọ́n má sì lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké. Ìbálòpọ̀ àti ìbímọlémọ wà lára ìjọsìn àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká. Bákan náà, ìbálòpọ̀ wà lára ohun táwọn ará Kénáánì máa ń ṣe nínú ìjọsìn wọn, tọkùnrin tobìnrin ló sì máa ń ṣe é. Èyí fa ìwà ìbàjẹ́ tó burú gan-an, ìwà yìí sì tàn kálẹ̀. Àmọ́ ní tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ńṣe ni Òfin Mósè mú kí wọ́n ya ìjọsìn Jèhófà sọ́tọ̀, láì pa á pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀.b Ọ̀nà míì tún wà tí Òfin yìí gbà ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní.
10 Àwọn òfin yẹn tún kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan.c Òótọ́ ni pé ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí jẹ́ ẹ̀bùn tí kò lábààwọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, síbẹ̀ ipasẹ̀ ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí ni ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù gbà ń tàn láti ìran kan dé òmíì. (Róòmù 5:12) Torí náà, ńṣe ni Òfin Ọlọ́run ń rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí pé inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí wọn sí. Ó ṣe tán, àtìgbà tí wọ́n ti bí wa ni gbogbo wa ti jogún ẹ̀ṣẹ̀. (Sáàmù 51:5) Àmọ́, ẹni mímọ́ ni Ọlọ́run jẹ́. Torí náà, ó dìgbà tí ẹnì kan bá rà wá pa dà, tí Ọlọ́run sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá ká tó lè sún mọ́ ọn.
11, 12. (a) Ìlànà pàtàkì wo ló túbọ̀ ṣe kedere nínú Òfin Mósè? (b) Àwọn nǹkan wo ni Òfin Mósè sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kí wọ́n lè máa ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́?
11 Òfin Mósè jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo. Òfin Mósè fi hàn pé tẹ́nì kan bá ṣẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ bá ẹni náà wí níbàámu pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀. Òfin náà sọ pé: “Kí o gba ẹ̀mí dípò ẹ̀mí, ojú dípò ojú, eyín dípò eyín, ọwọ́ dípò ọwọ́, ẹsẹ̀ dípò ẹsẹ̀.” (Diutarónómì 19:21) Torí náà, tí wọ́n bá ń ṣèdájọ́ ọ̀daràn kan, ìyà tó dọ́gba pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi jẹ ẹ́. Òfin Mósè jẹ́ ká rí i pé ìlànà yìí ṣe pàtàkì gan-an sí Jèhófà. Tá a bá sì lóye ìlànà yìí, á jẹ́ ká túbọ̀ mọ ìdí tí Jèhófà fi yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀ pé kó wá kú fún wa kó lè rà wá pa dà. A máa túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà ni Orí 14 ìwé yìí.—1 Tímótì 2:5, 6.
12 Òfin Mósè tún jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ bí wọ́n ṣe lè máa dájọ́ lọ́nà tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá fẹ̀sùn kan ẹnì kan, ó kéré tán ẹni méjì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí i, káwọn adájọ́ tó lè gbà pé ẹ̀sùn náà jẹ́ òótọ́. Tẹ́nì kan bá jẹ́rìí èké, ìyà kékeré kọ́ lẹni náà máa jẹ. (Diutarónómì 19:15, 18, 19) Yàtọ̀ síyẹn, Òfin Mósè ò fàyè gba káwọn èèyàn máa hùwà ìbàjẹ́ tàbí kí wọ́n máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. (Ẹ́kísódù 23:8; Diutarónómì 27:25) Kódà, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń ṣòwò, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà ìdájọ́ òdodo Jèhófà. (Léfítíkù 19:35, 36; Diutarónómì 23:19, 20) Ká sòótọ́, Òfin Mósè ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní gan-an!
Òfin Tó Kọ́ni Ní Ìdájọ́ Òdodo àti Àánú
13, 14. Báwo ni Òfin Mósè ṣe ń mú kí wọ́n dá ẹjọ́ ẹni tó jalè àti ẹni tí wọ́n jí nǹkan ẹ̀ lọ́nà tó tọ́?
13 Ṣé òfin tó le koko, tí kò sì fàyè gba àánú ni Òfin Mósè? Rárá o! Ọlọ́run mí sí Ọba Dáfídì láti kọ̀wé pé: “Òfin Jèhófà pé.” (Sáàmù 19:7) Ọba Dáfídì mọ̀ dáadáa pé Òfin Mósè kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa fi àánú hàn, kí wọ́n sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo. Báwo ni Òfin náà ṣe ṣe bẹ́ẹ̀?
14 Láwọn orílẹ̀-èdè kan lónìí, ó jọ pé òfin ń ṣe àwọn ọ̀daràn láǹfààní ju ẹni tí wọ́n hùwà àìdáa sí lọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ní kí ẹnì kan tó jalè lọ lo àsìkò kan lẹ́wọ̀n. Àmọ́, ẹni tí wọ́n jà lólè lè má rí ẹrù ẹ̀ gbà pa dà. Síbẹ̀, ẹni náà tún gbọ́dọ̀ máa san owó orí tí wọ́n máa ń lò láti fi bójú tó ọgbà ẹ̀wọ̀n tí olè náà wà àti oúnjẹ tó ń jẹ. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí bí nǹkan ṣe rí ní Ísírẹ́lì àtijọ́, torí pé Òfin Mósè ní àwọn ìlànà tó máa jẹ́ kí wọ́n gba ti ẹni tí wọ́n hùwà àìdáa sí rò, kí wọ́n má sì hùwà ìkà sí ọ̀daràn. Bí àpẹẹrẹ, kò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n nígbà yẹn, bó ṣe wà lóde òní. Òfin tún sọ pé ìyà tí wọ́n máa fi jẹ ọ̀daràn kan ò gbọ́dọ̀ pọ̀ jù. (Diutarónómì 25:1-3) Àmọ́, ẹni tó jalè gbọ́dọ̀ san ohun tó jí pa dà. Ó tún gbọ́dọ̀ fún ẹni tó jà lólè ní nǹkan kan láfikún sí ohun tó jí. Èló ni olè náà máa san? Ó máa ń yàtọ̀ síra. Ó jọ pé Jèhófà fún àwọn onídàájọ́ lómìnira láti ṣàyẹ̀wò bọ́rọ̀ náà bá ṣe rí, irú bíi bóyá ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ti ronú pìwà dà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìdí nìyẹn tí ohun tí Léfítíkù 6:1-7 sọ pé ẹni tó jalè máa san fi kéré sí ohun tí Ẹ́kísódù 22:7 sọ.
15. Báwo ni Òfin Mósè ṣe ń mú kí wọ́n dá ẹjọ́ tó tọ́ fún ẹni tó ṣèèṣì pa èèyàn, kí ẹni náà sì jàǹfààní àánú Ọlọ́run?
15 Òfin Mósè fi hàn pé aláàánú ni Jèhófà, ó gbà pé kì í ṣe gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ló jẹ́ àmọ̀ọ́mọ̀dá. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹni tó ṣèèṣì pa èèyàn bá tètè sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú ààbò tó wà káàkiri ilẹ̀ Ísírẹ́lì, wọn ò ní pa á láti fi ẹ̀mí ẹ̀ dípò ti ẹni tó pa. Lẹ́yìn táwọn onídàájọ́ tí Jèhófà yàn sípò bá ti gbé ẹjọ́ ẹni náà yẹ̀ wò, ó gbọ́dọ̀ máa gbé inú ìlú ààbò títí dìgbà tí àlùfáà àgbà fi máa kú. Lẹ́yìn náà, ó lè lọ gbé níbikíbi tó bá wù ú. Nípa bẹ́ẹ̀, ó máa jàǹfààní àánú Ọlọ́run. Bákan náà, òfin yìí jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i pé ẹ̀mí èèyàn ṣe pàtàkì gan-an sí Jèhófà.—Nọ́ńbà 15:30, 31; 35:12-25.
16. Báwo ni Òfin Mósè ṣe dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn?
16 Òfin Mósè kọ́ àwọn èèyàn pé ó yẹ kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíì. Àpẹẹrẹ kan ni bó ṣe ń dáàbò bo àwọn tó bá jẹ gbèsè. Òfin yìí sọ pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wọnú ilé ẹni tó jẹ gbèsè láti lọ fipá gba ohun tó fẹ́ fi ṣe ìdúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìta lẹni tó yá èèyàn ní nǹkan máa dúró sí títí dìgbà tẹ́ni tó jẹ gbèsè á fi mú ohun tó fẹ́ fi ṣe ìdúró wá fún un. Èyí fi hàn pé ẹnikẹ́ni ò kàn lè já wọ ilé onílé. Tó bá jẹ́ pé aṣọ àwọ̀lékè lẹni tó jẹ gbèsè náà fi ṣe ohun ìdúró, ẹni tó yá a ní nǹkan gbọ́dọ̀ dá a pa dà lálẹ́, torí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé aṣọ yẹn lẹni tó jẹ gbèsè náà fẹ́ fi bora sùn.—Diutarónómì 24:10-14.
17, 18. Tó bá dọ̀rọ̀ ogun jíjà, báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe yàtọ̀ sáwọn orílẹ̀-èdè tó kù, kí sì nìdí?
17 Jèhófà tún fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin tí wọ́n máa tẹ̀ lé nípa ogun jíjà. Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n jẹ́ arógunyọ̀ tàbí kí wọ́n máa jà torí kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn lágbára. Kàkà bẹ́ẹ̀, tí wọ́n bá fẹ́ ja “Àwọn Ogun Jèhófà” nìkan ni wọ́n máa ń lọ sójú ogun. (Nọ́ńbà 21:14) Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fún àwọn ọ̀tá wọn láǹfààní láti wá àlááfíà kí wọ́n má bàa bá wọn jagun. Táwọn èèyàn náà bá kọ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè wá gbógun tì wọ́n, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé òfin tí Ọlọ́run fún wọn nípa ogun jíjà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ fipá bá àwọn obìnrin lò pọ̀ tàbí kí wọ́n kàn bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn èèyàn nípakúpa bíi tàwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè míì. Kódà, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ gé àwọn igi eléso wọn dà nù tàbí kí wọ́n ba àyíká wọn jẹ́ lọ́nàkọnà.d Kò sí orílẹ̀-èdè kankan nígbà yẹn tó ń tẹ̀ lé irú òfin yìí tí wọ́n bá ń jagun.—Diutarónómì 20:10-15, 19, 20; 21:10-13.
18 Ṣé kì í bà ọ́ nínú jẹ́ tó o bá gbọ́ pé wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọdé níṣẹ́ ogun jíjà láwọn orílẹ̀-èdè kan? Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, ẹni tí kò bá tíì pé ọmọ ogún ọdún ò lè wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun. (Nọ́ńbà 1:2, 3) Kódà, tí ọkùnrin tó ti lé lógún ọdún bá ń bẹ̀rù jù, wọn ò ní fi dandan mú un pé kó lọ sójú ogun. Bákan náà, tí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, òfin sọ pé kò gbọ́dọ̀ lọ sójú ogun fún ọdún kan kó má bàa fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu, á sì lè wà nílé nígbà tí ìyàwó ẹ̀ bá bí àkọ́bí wọn. Òfin Mósè sọ pé èyí á jẹ́ kí ọkùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó náà “dúró sílé kó lè máa múnú ìyàwó rẹ̀ dùn.”—Diutarónómì 20:5, 6, 8; 24:5.
19. Báwo ni Òfin Mósè ṣe ń dáàbò bo àwọn obìnrin, ọmọdé, ìdílé, opó àtàwọn ọmọ aláìlóbìí?
19 Òfin Mósè tún jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n máa bójú tó àwọn obìnrin, ọmọdé àti ìdílé, kí wọ́n sì máa pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Jèhófà pàṣẹ fáwọn òbí pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn láwọn nǹkan táá mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ òun. (Diutarónómì 6:6, 7) Jèhófà tún sọ pé àwọn ìbátan ò gbọ́dọ̀ bá ara wọn lò pọ̀, tírú ẹ̀ bá sì ṣẹlẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa pa àwọn tó ṣe é. (Léfítíkù, orí 18) Bákan náà, Jèhófà sọ pé àwọn tó ti ṣègbéyàwó ò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì, torí pé ńṣe nìyẹn máa ń tú ìdílé ká, kì í sì í jẹ́ kí àwọn tó wà nínú ìdílé ní iyì àti ìbàlẹ̀ ọkàn. Òfin Mósè jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn opó àti ọmọ aláìlóbìí ká Jèhófà lára, kódà ó fi àwọn ọ̀rọ̀ tó lágbára gan-an kìlọ̀ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ wọ́n.—Ẹ́kísódù 20:14; 22:22-24.
20, 21. (a) Kí nìdí tí Òfin Mósè fi fàyè gbà á pé káwọn ọkùnrin fẹ́ ju ìyàwó kan lọ? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi fàyè gbà á pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa kọ aya wọn sílẹ̀ kí Jésù tó dé?
20 Ní báyìí tá a ti mọ̀ pé Òfin Mósè ń dáàbò bo àwọn obìnrin, ọmọdé, ìdílé, opó àtàwọn ọmọ aláìlóbìí, àwọn kan lè wá máa ronú pé, ‘Kí nìdí tí Òfin Mósè fi fàyè gbà á pé káwọn ọkùnrin máa fẹ́ ju ìyàwó kan lọ?’ (Diutarónómì 21:15-17) Ó yẹ ká ronú nípa bí nǹkan ṣe rí láyé nígbà tí Jèhófà fún wọn lófin yẹn. Torí pé àṣà wọn àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan nígbà yẹn yàtọ̀ sí tòde òní. (Òwe 18:13) Nígbà tí Jèhófà dá ìgbéyàwó sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, ohun tó fẹ́ ni pé kí ọkùnrin kan fẹ́ aya kan, káwọn méjèèjì sì máa wà pa pọ̀ títí láé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18, 20-24) Àmọ́, nígbà tí Jèhófà fi máa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lófin, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọkùnrin wọn ló ti fẹ́ ju ìyàwó kan lọ, èyí sì ti ń ṣẹlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. Jèhófà mọ̀ pé “alágídí” làwọn èèyàn yẹn, kódà ó mọ̀ pé wọ́n á máa rú àwọn òfin tó ṣe pàtàkì jù lọ, irú bí èyí tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ bọ̀rìṣà. (Ẹ́kísódù 32:9) Torí náà, Jèhófà rí i pé kò tíì tó àsìkò tóun máa ṣàtúnṣe gbogbo àṣàkaṣà tí wọ́n ti mú wọnú ìgbéyàwó. Àmọ́, ẹ rántí pé Jèhófà kọ́ ló ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fẹ́ ju ìyàwó kan lọ. Síbẹ̀, ó lo Òfin Mósè láti fi dáàbò bo àwọn obìnrin, káwọn ọkùnrin má bàa máa hùwà àìdáa sí wọn.
21 Bákan náà, Òfin Mósè gbà kí ọkùnrin kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ lórí oríṣiríṣi ẹ̀sùn tó burú gan-an. (Diutarónómì 24:1-4) Jésù sọ pé “torí pé ọkàn [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] le” ni Ọlọ́run fi gbà kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, àsìkò díẹ̀ ni Jèhófà fi fàyè gbà á pé kí wọ́n máa kọ ìyàwó wọn sílẹ̀. Torí pé nígbà tí Jésù wá sáyé, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà tí Jèhófà fi lélẹ̀ nígbà tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀.—Mátíù 19:8.
Òfin Mósè Kọ́ni Pé Ìfẹ́ Ṣe Pàtàkì Gan-an
22. Àwọn ọ̀nà wo ni Òfin Mósè gbà fúnni níṣìírí pé ó yẹ ká máa fìfẹ́ hàn, àwọn wo ló sì sọ pé ká máa fìfẹ́ hàn sí?
22 Lónìí, kò sí orílẹ̀-èdè tó lófin tó ń kọ́ni pé ó yẹ kéèyàn máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Àmọ́, Òfin Mósè kọ́ni pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an. Kódà, nínú ìwé Diutarónómì nìkan, ó ju ogún (20) ìgbà lọ tí ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” fara hàn lóríṣiríṣi ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, òfin kejì tó ga jù lọ nínú Òfin Mósè sọ pé: “O . . . gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.” (Léfítíkù 19:18; Mátíù 22:37-40) Kì í ṣe ara wọn nìkan ni òfin yìí sọ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́, àmọ́ ó tún sọ pé ó yẹ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì tó wà láàárín wọn, kí wọ́n máa rántí pé àwọn náà ti fìgbà kan rí jẹ́ àjèjì. Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìní àtàwọn ẹni tíyà ń jẹ, kí wọ́n pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn, kí wọ́n má sì fìyà jẹ wọ́n torí pé wọn ò lẹ́ni tó máa gbèjà wọn. Kódà, Òfin tún sọ pé kí wọ́n máa ṣenúure sáwọn ẹranko, kí wọ́n sì máa gba tiwọn rò.—Ẹ́kísódù 23:6; Léfítíkù 19:14, 33, 34; Diutarónómì 22:4, 10; 24:17, 18.
23. Kí ni ìfẹ́ tí onísáàmù kan ní fún òfin Ọlọ́run mú kó ṣe, kí làwa náà lè pinnu láti ṣe?
23 Kò sí orílẹ̀-èdè kankan tó ní òfin tó ń ṣeni láǹfààní bí òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Abájọ tí onísáàmù kan fi sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!” Kì í ṣe pé ó kàn sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà. Àmọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ òfin náà, ó wù ú kó máa pa á mọ́ nígbà gbogbo. Ó tún sọ pé: “Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ronú lé e lórí.” (Sáàmù 119:11, 97) Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òfin Jèhófà déédéé, ó sì dájú pé ìyẹn mú kó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn òfin náà. Bákan náà, ìyẹn mú kó túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Afúnnilófin náà. Tíwọ náà bá ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà, Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo àti Afúnnilófin tó ga jù lọ, ìfẹ́ tó o ní fún un á máa lágbára sí i, èyí á sì mú kó o túbọ̀ máa sún mọ́ ọn.
a Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ pẹ́ tí Òfin Ọlọ́run ti ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa bo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọ́n máa sé ẹni tó ní àrùn mọ́ àti pé kí ẹni tó bá fọwọ́ kan òkú rí i pé òun wẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀ṣẹ̀ lóye ìdí tó fi yẹ káwọn èèyàn máa ṣe bẹ́ẹ̀.—Léfítíkù 13:4-8; Nọ́ńbà 19:11-13, 17-19; Diutarónómì 23:13, 14.
b Àwọn ọmọ Kénáánì máa ń ní yàrá kan nínú tẹ́ńpìlì wọn táwọn tó wá jọ́sìn níbẹ̀ ti lè ní ìbálòpọ̀. Àmọ́, Òfin Mósè sọ pé tẹ́nì kan bá ní ìbálòpọ̀, ó máa di aláìmọ́ láàárín àkókò kan, kò sì gbọ́dọ̀ wọnú tẹ́ńpìlì. Torí náà, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń pa òfin yìí mọ́, wọn ò ní fi ìbálòpọ̀ kún ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe nínú ilé Jèhófà.
c Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí Òfin wà fún ni pé kó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Kódà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé ohun tí toh·rahʹ tí wọ́n máa ń pe “òfin” lédè Hébérù túmọ̀ sí ni “ìtọ́ni.”
d Nínú Òfin Mósè, Ọlọ́run béèrè pé: “Ṣé ó yẹ kí o gbógun ti igi inú igbó bí ẹni ń gbógun ti èèyàn ni?” (Diutarónómì 20:19) Nígbà tí Júù kan tó ń jẹ́ Philo, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ń ṣàlàyé òfin yìí, ó sọ pé: “Táwọn èèyàn bá ń jà, tí wọ́n wá lọ ń fìkanra mọ́ àwọn nǹkan tó wà láyìíká wọn láìṣe pé àwọn nǹkan náà ṣẹ̀ wọ́n, ìwà àìtọ́ ni wọ́n hù yẹn” lójú Ọlọ́run.
-
-
Jèhófà Pèsè “Ìràpadà ní Pàṣípààrọ̀ fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 14
Jèhófà Pèsè “Ìràpadà ní Pàṣípààrọ̀ fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn”
1, 2. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàlàyé ipò táwa èèyàn wà, kí sì ni ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó wà fún wa?
“GBOGBO ìṣẹ̀dá jọ ń kérora nìṣó, wọ́n sì jọ wà nínú ìrora.” (Róòmù 8:22) Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ yìí ṣàlàyé ipò tó ń bani nínú jẹ́ táwa èèyàn wà. Lójú àwa èèyàn, ó lè dà bíi pé a ò lè bọ́ lọ́wọ́ ìyà, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àmọ́ Jèhófà ò dà bí àwa èèyàn lásánlàsàn, kò sóhun tó ṣòro fún un láti ṣe. (Nọ́ńbà 23:19) Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ó sì ti ṣe ọ̀nà àbáyọ ká lè bọ́ lọ́wọ́ ìpọ́njú tó ń dojú kọ wá. Ìràpadà lọ̀nà àbáyọ náà.
2 Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù tí Jèhófà fún àwa èèyàn ni ìràpadà. Ẹ̀bùn yìí ló mú ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Éfésù 1:7) Bákan náà, ìràpadà ló jẹ́ ká lè ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, ì báà jẹ́ ní ọ̀run tàbí nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43; Jòhánù 3:16; 1 Pétérù 1:4) Àmọ́, kí ni ìràpadà? Kí ló sì kọ́ wa nípa ìdájọ́ òdodo tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà?
Ìdí Tá A Fi Nílò Ìràpadà
3. (a) Kí nìdí tá a fi nílò ìràpadà? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi yí ìdájọ́ ikú tó ṣe fún àwọn ọmọ Ádámù pa dà?
3 Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ló mú ká nílò ìràpadà. Ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, torí náà àìsàn, ìbànújẹ́, ìrora àti ikú ni ogún tó fi sílẹ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; Róòmù 8:20) Ọlọ́run ò yí ìdájọ́ ikú tó ṣe fún wọn pa dà. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ó tẹ òfin ara rẹ̀ lójú nìyẹn, ìyẹn òfin tó sọ pé: “Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 6:23) Tí Jèhófà ò bá sì tẹ̀ lé òfin tóun fúnra rẹ̀ gbé kalẹ̀, ìyẹn máa dá wàhálà sílẹ̀ torí àwọn áńgẹ́lì àtàwọn èèyàn ò ní rídìí tó fi yẹ kí wọ́n máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
4, 5. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, kí sì nìdí tó fi yẹ kí Jèhófà wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà? (b) Ẹ̀sùn wo ni Sátánì fi kan àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà?
4 Bá a ṣe rí i ní Orí 12, ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì tún fa ìṣòro míì tó le gan-an. Sátánì kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. Ó sọ pé òpùrọ́ àti ìkà ni Jèhófà, bákan náà ó sọ pé Jèhófà máa ń fi òmìnira du àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Nígbà tí Sátánì mú kí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, ńṣe ni Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ pé Ọlọ́run ò ní lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn pé àwọn olódodo á máa gbé ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Àìsáyà 55:10, 11) Ká ní Jèhófà ò ṣe nǹkan kan sọ́rọ̀ yìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn áńgẹ́lì àtàwọn èèyàn ò ní fọkàn tán an mọ́, wọn ò sì ní gbà pé àkóso ẹ̀ ló dáa jù.
5 Sátánì tún ba àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lórúkọ jẹ́. Ó fẹ̀sùn kàn wọ́n pé ohun tí wọ́n ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló ń mú kí wọ́n sìn ín àti pé tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro, wọn ò ní jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run mọ́. (Jóòbù 1:9-11) Ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì ju gbogbo ìṣòro tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà fáwa èèyàn. Torí náà, Jèhófà rí i pé ó yẹ kóun ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan òun. Àmọ́, báwo ni Ọlọ́run ṣe máa yanjú ọ̀ràn yìí, tá á sì tún gba àwa èèyàn là?
Ìràpadà Ṣe Rẹ́gí Pẹ̀lú Ohun Tá A Pàdánù
6. Oríṣiríṣi ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà ṣàpèjúwe ohun tí Ọlọ́run ṣe kó lè gba àwa èèyàn là?
6 Ohun tí Jèhófà ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé onídàájọ́ òdodo àti aláàánú ni. Ohun tó ṣe náà rọrùn, ó sì mọ́gbọ́n dání. Kò séèyàn kankan tó lè ronú ẹ̀ láé. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Bíbélì gbà ṣàpèjúwe ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé Ọlọ́run rà wá tàbí mú ká bá òun rẹ́, Bíbélì tún pè é ní ẹbọ ìpẹ̀tù àti ètùtù. (Sáàmù 49:8; Dáníẹ́lì 9:24; Gálátíà 3:13; Kólósè 1:20; Hébérù 2:17) Àmọ́ nínú gbogbo wọn, ọ̀rọ̀ tí Jésù fi ṣàpèjúwe ẹ̀ ló bá a mu jù lọ. Ó sọ pé: “Ọmọ èèyàn ò . . . wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́, kó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà [Gíríìkì, lyʹtron] ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”—Mátíù 20:28.
7, 8. (a) Kí ni “ìràpadà” túmọ̀ sí nínú Ìwé Mímọ́? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìràpadà túmọ̀ sí ohun tó ṣe rẹ́gí?
7 Kí ni ìràpadà? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò nínú ohun tí Jésù sọ yìí wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó túmọ̀ sí “láti tú sílẹ̀ tàbí láti dá sílẹ̀.” Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí láti fi ṣàpèjúwe owó tí wọ́n máa ń san káwọn ọ̀tá lè tú àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú sílẹ̀. Torí náà, a lè sọ pé ìràpadà túmọ̀ sí ohun tá a san láti fi ra ohun kan pa dà. Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò fún “ìràpadà” (ìyẹn koʹpher) wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó túmọ̀ sí “bo [nǹkan] mọ́lẹ̀.” Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ fún Nóà pé kó fi ọ̀dà bítúmẹ́nì “bo” (ìyẹn koʹpher) inú àti ìta áàkì. (Jẹ́nẹ́sísì 6:14) Èyí jẹ́ ká rí i pé ohun míì tí ìràpadà túmọ̀ sí ni láti bo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.
8 Ìwé Theological Dictionary of the New Testament sọ pé ọ̀rọ̀ náà (koʹpher) “túmọ̀ sí kí nǹkan bára mu,” tàbí kó ṣe rẹ́gí. Torí náà, láti san ìràpadà tàbí pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́, ó di dandan ká rí ohun kan tó bára mu tàbí tó ṣe rẹ́gí, táá lè kájú ohun tá a ti pàdánù. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi fún Ísírẹ́lì ní òfin tó sọ pé: “Kí o gba ẹ̀mí dípò ẹ̀mí, ojú dípò ojú, eyín dípò eyín, ọwọ́ dípò ọwọ́, ẹsẹ̀ dípò ẹsẹ̀.”—Diutarónómì 19:21.
9. Kí nìdí táwọn ẹni ìgbàgbọ́ fi ń fi ẹran rúbọ, ojú wo ni Jèhófà sì fi wo irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀?
9 Látìgbà ayé Ébẹ́lì làwọn ẹni ìgbàgbọ́ ti máa ń fi ẹran rúbọ sí Ọlọ́run. Ohun tí ẹbọ tí wọ́n ń rú yìí ń fi hàn ni pé wọ́n mọ̀ pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tó nílò ìràpadà. Ó tún fi hàn pé wọ́n gbára lé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa gba aráyé là nípasẹ̀ “ọmọ” rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 4:1-4; Léfítíkù 17:11; Hébérù 11:4) Inú Jèhófà dùn sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀, ó sì ka àwọn olùjọsìn yẹn sí ẹni rere. Àmọ́, ẹran táwọn èèyàn fi ń rúbọ kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, torí pé àwọn ẹranko rẹlẹ̀ sí àwa èèyàn. (Sáàmù 8:4-8) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ kò lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.” (Hébérù 10:1-4) Ńṣe ni ẹbọ táwọn èèyàn ń rú nígbà yẹn wulẹ̀ ń ṣàpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe máa fi ìràpadà mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá.
“Ìràpadà Tó Bá A Mu Rẹ́gí”
10. (a) Ta ni ẹni tó máa san ìràpadà náà ní láti bá dọ́gba, kí sì nìdí? (b) Kí nìdí tí kò fi pọn dandan kí ọ̀pọ̀ èèyàn kú ká tó lè ra àwọn ọmọ Ádámù pa dà?
10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo èèyàn . . . ń kú nínú Ádámù.” (1 Kọ́ríńtì 15:22) Torí náà, ká tó lè san ìràpadà, ẹnì kan tó jẹ́ ẹni pípé bíi ti Ádámù gbọ́dọ̀ kú. (Róòmù 5:14) Èyí ló máa yanjú ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó bá ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run mu, torí ẹni pípé tí kò jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú látọ̀dọ̀ Ádámù nìkan ló lè fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ láti san “ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí” pẹ̀lú ohun tí Ádámù gbé sọ nù. (1 Tímótì 2:6) Àmọ́, ṣé ó pọn dandan kí àìmọye èèyàn tó jẹ́ ẹni pípé kú ká tó lè ra ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Ádámù pa dà? Rárá o! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ẹnì kan [Ádámù] wọ ayé, . . . ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Torí náà, “bí ikú ṣe wá nípasẹ̀ ẹnì kan,” Ọlọ́run náà gba aráyé là “nípasẹ̀ ẹnì kan.” (1 Kọ́ríńtì 15:21) Báwo ni Jèhófà ṣe ṣe é?
“Ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí fún gbogbo èèyàn”
11. (a) Báwo lẹni tó fẹ́ san ìràpadà ṣe máa “tọ́ ikú wò fún gbogbo èèyàn”? (b) Kí nìdí tí ìràpadà náà ò fi lè dá Ádámù àti Éfà sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
11 Jèhófà ṣètò pé kí ọkùnrin pípé kan fínnú-fíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ. Bí Róòmù 6:23 ṣe sọ, “ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀.” Torí náà, ẹni tó fẹ́ san ìràpadà náà gbọ́dọ̀ “tọ́ ikú wò fún gbogbo èèyàn,” ìyẹn ni pé ó máa san gbèsè táwa èèyàn jẹ torí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. (Hébérù 2:9; 2 Kọ́ríńtì 5:21; 1 Pétérù 2:24) Ìyẹn máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní tó pọ̀ gan-an. Torí ìràpadà máa fagi lé ìdájọ́ ikú tó wà lórí àwọn ọmọ Ádámù tó jẹ́ onígbọràn, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ò sì ní lágbára kankan lórí wọn mọ́ láé.a—Róòmù 5:16.
12. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé gbèsè tẹ́nì kan ṣoṣo san lè ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní.
12 Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé ilé iṣẹ́ ńlá kan wà nílùú tó ò ń gbé tó sì jẹ́ pé ibẹ̀ lọ̀pọ̀ èèyàn ti ń ṣiṣẹ́. Ilé iṣẹ́ náà ń san owó tó jọjú fún ìwọ àtàwọn òṣìṣẹ́ tó kù, torí náà ẹ̀ ń gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn. Àmọ́, ọ̀gá ilé iṣẹ́ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í kówó jẹ, ni ilé iṣẹ́ náà bá wọko gbèsè. Bó ṣe di pé wọ́n ti ilé iṣẹ́ náà pa nìyẹn. Torí náà, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ìwọ àtàwọn òṣìṣẹ́ tó kù, èyí wá mú kó nira fún yín láti rí owó ilé àti owó iná san, títí kan owó omi àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì. Ìwà ìbàjẹ́ tí ọkùnrin yẹn hù fa ìṣòro fún gbogbo àwọn tí ilé iṣẹ́ náà jẹ ní gbèsè. Ṣé ọ̀nà àbáyọ kankan wà fáwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn? Bẹ́ẹ̀ ni! Olówó kan tó lójú àánú dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó mọ̀ pé ilé iṣẹ́ yẹn wúlò gan-an, ó sì káàánú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ àti ìdílé wọn. Torí náà, ó san gbèsè tí ilé iṣẹ́ náà jẹ, ó sì ní kí wọ́n ṣí i. Ohun tó ṣe yẹn mú kí ara tu àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ náà àti ìdílé wọn, títí kan àwọn tí wọ́n jẹ ní gbèsè. Bákan náà, Jésù san gbèsè tí Ádámù jẹ, ìyẹn sì ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní.
Ta Ló Pèsè Ìràpadà Náà?
13, 14. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè ìràpadà fún wa? (b) Ta ló gba ìràpadà náà, kí sì nìdí tó fi yẹ kó rí bẹ́ẹ̀?
13 Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè pèsè “Ọ̀dọ́ Àgùntàn . . . tó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòhánù 1:29) Àmọ́ o, kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn ní kí ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì wá gba aráyé là. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tó máa lè dáhùn gbogbo ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́nà tó dáa jù ni Jèhófà rán wá. Ohun tó ṣeyebíye jù lọ sí Jèhófà lọ̀rọ̀ yìí ná an! Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tó jẹ́ “àrídunnú rẹ̀ lójoojúmọ́” ló rán wá. (Òwe 8:30) Ọmọ Ọlọ́run yìí fínnú-fíndọ̀ “fi gbogbo ohun tó ní sílẹ̀,” títí kan gbogbo ògo tó ní lọ́run. (Fílípì 2:7) Jèhófà wá ṣe iṣẹ́ ìyanu kan, ó fi ẹ̀mí àkọ́bí Ọmọ ẹ̀ yìí sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá Júù kan tó ń jẹ́ Màríà. (Lúùkù 1:27, 35) Jésù ni wọ́n sọ ọ́ nígbà tí wọ́n bí i. Àmọ́, Bíbélì tún pè é ní Ádámù ìkẹyìn, torí pé ẹni pípé lòun náà bíi ti Ádámù. (1 Kọ́ríńtì 15:45, 47) Torí náà, Jésù lè fi ara rẹ̀ rúbọ láti ra àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà.
14 Ta la máa san ìràpadà yẹn fún? Sáàmù 49:7 sọ pé “Ọlọ́run” ló máa gba ìràpadà náà. Àmọ́, ṣebí Jèhófà fúnra ẹ̀ ló fún wa ní ìràpadà yẹn? Òun ni lóòótọ́, àmọ́ ìyẹn ò sọ ìràpadà di ohun tí kò nítumọ̀, bí ìgbà téèyàn mú owó jáde nínú àpò ọ̀tún tó sì fi sínú àpò òsì. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ìràpadà kì í kàn ṣe pàṣípààrọ̀ ohun kan tó ṣe é fojú rí. Kàkà bẹ́ẹ̀ ọ̀rọ̀ òfin ni, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo. Bí Jèhófà ṣe fún wa ní Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n láti san ìràpadà náà jẹ́ ká rí i pé ìgbà gbogbo ló máa ń ṣe ohun tó bá ìlànà ìdájọ́ òdodo rẹ̀ mu, tíyẹn bá tiẹ̀ máa ná an ní ohun tó pọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 22:7, 8, 11-13; Hébérù 11:17; Jémíìsì 1:17.
15. Kí nìdí tó fi pọn dandan kí Jésù jìyà kó sì kú?
15 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù Kristi gbà kí wọ́n fìyà jẹ òun kó lè san ìràpadà náà. Ó jẹ́ kí wọ́n fàṣẹ ọba mú òun, lẹ́yìn náà wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án, wọ́n dá a lẹ́bi, wọ́n sì kàn án mọ́ òpó igi oró. Ṣé ó pọn dandan kí Jésù jẹ ìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, torí èyí ló máa jẹ́ kó ṣe kedere pé irọ́ ni Sátánì ń pa nígbà tó sọ pé kò sí ìránṣẹ́ Jèhófà kankan tó máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Ọlọ́run dáàbò bo Jésù nígbà tó wà lọ́mọdé kí Hẹ́rọ́dù má bàa rí i pa. (Mátíù 2:13-18) Àmọ́ nígbà tí Jésù dàgbà, ó lè fara da gbogbo àtakò Sátánì torí pé wàhálà tí Sátánì dá sílẹ̀ yé e dáadáa.b Nǹkan kékeré kọ́ ni wọ́n fojú Jésù rí, síbẹ̀ ó jẹ́ “adúróṣinṣin, aláìṣẹ̀, aláìlẹ́gbin” àti “ẹni tí a yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” Ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà láwọn ìránṣẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́ sí i lójú inúnibíni. (Hébérù 7:26) Abájọ tó fi jẹ́ pé kí Jésù tó kú, ó ké jáde pé: “A ti ṣe é parí!”—Jòhánù 19:30.
Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìràpadà Náà Parí
16, 17. (a) Kí ni Jésù ṣe kó lè ṣe iṣẹ́ ìràpadà náà parí? (b) Kí nìdí tó fi pọn dandan fún Jésù láti fara hàn “níwájú Ọlọ́run nítorí wa”?
16 Àmọ́ o, Jésù ò tíì ṣe iṣẹ́ ìràpadà náà parí. Ní ọjọ́ kẹta tí Jésù kú, Jèhófà jí i dìde. (Ìṣe 3:15; 10:40) Bí Jèhófà ṣe jí Ọmọ rẹ̀ dìde mú kó lè san èrè fún un torí pé ó jẹ́ olóòótọ́. Ìyẹn tún mú kó ṣeé ṣe fún Jésù tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà Ọlọ́run láti ṣe àwọn nǹkan tó kù tó yẹ kó ṣe ká lè jàǹfààní ìràpadà tó san. (Róòmù 1:4; 1 Kọ́ríńtì 15:3-8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó ṣe náà, ó sọ pé: “Nígbà tí Kristi dé bí àlùfáà àgbà . . . , kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ ọmọ màlúù ló gbé wọnú ibi mímọ́, àmọ́ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀ ni, lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó sì gba ìtúsílẹ̀ àìnípẹ̀kun fún wa. Torí Kristi ò wọnú ibi mímọ́ tí wọ́n fi ọwọ́ ṣe, tó jẹ́ àpẹẹrẹ ohun gidi, àmọ́ ọ̀run gangan ló wọ̀ lọ, tó fi jẹ́ pé ó ń fara hàn báyìí níwájú Ọlọ́run nítorí wa.”—Hébérù 9:11, 12, 24.
17 Kì í ṣe pé Kristi gbé ẹ̀jẹ̀ ara ẹ̀ lọ sọ́run. (1 Kọ́ríńtì 15:50) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ̀jẹ̀ náà dúró fún ló gbé lọ, ìyẹn ẹ̀tọ́ tó ní láti máa gbé ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn pípé. Lẹ́yìn náà, ó san ìràpadà ní ti pé ó gbé ẹ̀tọ́ tó ní láti máa gbé ayé lọ síwájú Ọlọ́run lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kó lè fi ṣe pàṣípààrọ̀ nítorí àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀. Ṣé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, ìgbà yẹn ni Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ jáde sórí ọgọ́fà (120) ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 2:1-4) Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wúni lórí lóòótọ́, àmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ nìyẹn kàn jẹ́ lára àwọn nǹkan àgbàyanu tí Ọlọ́run máa ṣe fún wa torí ìràpadà náà.
Àǹfààní Ìràpadà
18, 19. (a) Àwùjọ méjì wo ló jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi? (b) Ọ̀nà wo ni ìràpadà máa gbà ṣe àwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” láǹfààní ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú?
18 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kólósè, ó sọ pé ẹbọ ìràpadà Kristi ló mú kí Ọlọ́run gbà káwa èèyàn pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwùjọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa jàǹfààní ẹbọ ìràpadà náà, ó pè wọ́n ní “àwọn ohun tó wà ní ọ̀run” àti “àwọn ohun tó wà ní ayé.” (Kólósè 1:19, 20; Éfésù 1:10) Àwọn tó wà nínú àwùjọ àkọ́kọ́ ni àwọn Kristẹni tó nírètí láti lọ sí ọ̀run kí wọ́n lè di àlùfáà, kí wọ́n sì bá Kristi Jésù jọba lé ayé lórí. Iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000). (Ìfihàn 5:9, 10; 7:4; 14:1-3) Wọ́n máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jésù fún ẹgbẹ̀rún ọdún, káwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn lè jàǹfààní ìràpadà, títí wọ́n á fi di pípé.—1 Kọ́ríńtì 15:24-26; Ìfihàn 20:6; 21:3, 4.
19 “Àwọn ohun tó wà ní ayé” ni àwọn èèyàn tó nírètí láti gbádùn ayé títí láé nínú Párádísè. Ìfihàn 7:9-17 pè wọ́n ní “ogunlọ́gọ̀ èèyàn,” wọ́n sì máa la “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀ já. Àmọ́, kò dìgbà tí wọ́n bá la ìpọ́njú ńlá já kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í jàǹfààní ìràpadà náà. Ní báyìí, wọ́n “ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Torí pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà, wọ́n ń jàǹfààní àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ń ṣe fún wọn ní báyìí. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà kà wọ́n sí olódodo, ó sì pè wọ́n ní ọ̀rẹ́ rẹ̀! (Jémíìsì 2:23) Ẹbọ ìràpadà Jésù mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ‘sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ ní fàlàlà.’ (Hébérù 4:14-16) Tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run máa dárí jì wọ́n. (Éfésù 1:7) Bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, wọ́n lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Hébérù 9:9; 10:22; 1 Pétérù 3:21) Torí náà, kò dìgbà tí Párádísè bá dé kí wọ́n tó lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀ ní báyìí! (2 Kọ́ríńtì 5:19, 20) Tó bá sì di ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Ọlọ́run máa bù kún wọn gan-an. Díẹ̀díẹ̀, ó máa jẹ́ kí wọ́n dẹni tá a “dá . . . sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹrú ìdíbàjẹ́” lẹ́yìn náà wọ́n máa “ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.
20. Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tó o bá ń ronú nípa ìràpadà?
20 “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi” torí ìràpadà náà! (Róòmù 7:25) Ó jọni lójú gan-an láti rí i pé ohun tó rọrùn tó sì bọ́gbọ́n mu ni Jèhófà ṣe láti gba àwa èèyàn là. (Róòmù 11:33) Tá a bá ń ronú nípa ìràpadà náà, àá túbọ̀ mọyì Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ onídàájọ́ òdodo, èyí á sì mú kó wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn. Bíi ti onísáàmù náà, ó yẹ káwa náà máa yin Jèhófà torí pé ó “nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.”—Sáàmù 33:5.
a Ìràpadà náà ò lè dá Ádámù àti Éfà sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ohun tí Òfin Mósè sọ nípa ẹni tó bá mọ̀ọ́mọ̀ pa èèyàn ni pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ gba ìràpadà fún ẹ̀mí apààyàn tí ikú tọ́ sí.” (Nọ́ńbà 35:31) Ó dájú pé ikú tọ́ sí Ádámù àti Éfà torí pé ńṣe ni wọ́n yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé ohun tí wọ́n ṣe náà ò dáa. Torí náà, wọ́n pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti wà láàyè títí láé.
b Kí Jésù tó lè san ìràpadà tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ohun tí Ádámù sọ nù, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni pípé tó ti dàgbà nígbà tó bá máa kú, kì í ṣe ọmọ kékeré. Rántí pé ṣe ni Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, ó mọ̀ pé ohun tóun ṣe ò dáa àti pé Jèhófà máa fìyà jẹ òun tóun bá ṣe é. Torí náà, kí Jésù tó lè di “Ádámù ìkẹyìn” kó sì bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀, ó ti ní láti dàgbà torí ìyẹn lá jẹ́ kó mọ ohun tó ń ṣe, kó sì pinnu pé òun máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. (1 Kọ́ríńtì 15:45, 47) Nípa bẹ́ẹ̀, bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀ àti bó ṣe kú torí àwa èèyàn jẹ́ “ìwà òdodo kan.”—Róòmù 5:18, 19.
-
-
Jésù “Fìdí Ìdájọ́ Òdodo Múlẹ̀ ní Ayé”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 15
Jésù “Fìdí Ìdájọ́ Òdodo Múlẹ̀ ní Ayé”
1, 2. Ìgbà wo ni Jésù bínú, kí sì nìdí?
LỌ́JỌ́ kan, Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì, ó sì rí ohun tó bí i nínú gan-an. Ó lè ṣòro láti gbà gbọ́ pé Jésù bínú, ó ṣe tán èèyàn jẹ́jẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà ni. (Mátíù 21:5) Àmọ́, inú tó bí Jésù ò mú kó ṣe ohun tí ò dáa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìtara tó ní láti ṣe ohun tó tọ́ ló mú kó bínú nígbà tó rí i táwọn èèyàn ń hùwà ìrẹ́jẹ tó burú gan-an.a
2 Jésù fẹ́ràn tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù gan-an. Láyé ìgbà yẹn, ibẹ̀ nìkan ló jẹ́ ibi mímọ́ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti máa jọ́sìn Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Àwọn Júù máa ń wá síbẹ̀ láti ibi tó jìnnà gan-an kí wọ́n lè jọ́sìn. Kódà, àwọn Kèfèrí tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń wá síbẹ̀ kí wọ́n lè jọ́sìn ní àgbàlá tẹ́ńpìlì, níbi tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún wọn láti máa lò. Àmọ́, nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó lọ sínú tẹ́ńpìlì, ó sì rí àwọn nǹkan tó kó o nírìíra gan-an níbẹ̀. Ibẹ̀ ò dà bí ilé ìjọsìn rárá, ṣe ló dà bí ọjà! Ṣe làwọn oníṣòwò àtàwọn tó ń pààrọ̀ owó kún ibẹ̀ fọ́fọ́. Kí ló wá burú nínú ìyẹn? Ó burú torí pé ńṣe làwọn èèyàn yẹn ń wá sínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run kí wọ́n lè rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, kí wọ́n sì jà wọ́n lólè. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?—Jòhánù 2:14.
3, 4. Báwo làwọn kan ṣe ń rẹ́ni jẹ nínú tẹ́ńpìlì, kí ni Jésù sì ṣe nípa ẹ̀?
3 Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn pàṣẹ pé oríṣi owó ẹyọ kan pàtó ni káwọn èèyàn máa fi san owó orí ní tẹ́ńpìlì. Torí náà, àwọn tó bá wá sí tẹ́ńpìlì láti ọ̀nà jíjìn ní láti pààrọ̀ owó wọn kí wọ́n tó lè ní irú owó ẹyọ bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn táwọn tó ń pààrọ̀ owó fi dìídì gbé tábìlì wọn wá sínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì ń gbowó lọ́wọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n tó bá wọn pààrọ̀ owó wọn. Ẹran ọ̀sìn làwọn míì ń tà ní tiwọn, wọ́n sì ń rí owó rẹpẹtẹ nídìí ẹ̀. Kì í ṣe pé àwọn tó bá fẹ́ rúbọ ò lè rí ẹran rà lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò míì nínú ìlú, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì lè sọ pé kò ṣeé fi rúbọ. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ inú tẹ́ńpìlì ni wọ́n ti ra ẹran náà, ó dájú pé wọ́n máa fi rúbọ. Àwọn oníṣòwò yẹn mọ̀ pé ó di dandan káwọn èèyàn ra ẹran lọ́wọ́ àwọn, torí náà wọ́n máa ń gbówó lé e.b Kódà, kì í ṣe pé wọ́n kàn gbówó lé ohun tí wọ́n ń tà, ṣe ni wọ́n ń ja àwọn èèyàn lólè.
4 Jésù ò lè fara mọ́ ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn yẹn ń hù. Ó tún wá lọ jẹ́ pé inú ilé Bàbá rẹ̀ ni wọ́n ti ń hùwàkiwà náà! Ló bá fi okùn ṣe ẹgba, ó sì fi lé àwọn màlúù àti àgùntàn tí wọ́n ń tà jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì. Lẹ́yìn náà, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń pààrọ̀ owó, ó sì dojú àwọn tábìlì wọn dé. Fojú inú wo bí owó ẹyọ wọn á ṣe máa fọ́n káàkiri ilẹ̀ tó ń dán gbinrin yẹn! Lẹ́yìn ìyẹn, ó pàṣẹ fáwọn tó ń ta àdàbà pé: “Ẹ kó àwọn nǹkan yìí kúrò níbí!” (Jòhánù 2:15, 16) Jésù fìgboyà sọ̀rọ̀ débi pé kò sẹ́ni tó lè ta kò ó.
“Ẹ kó àwọn nǹkan yìí kúrò níbí!”
Ẹní Bíni Làá Jọ
5-7. (a) Kí ló mú kí Jésù nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, kí làwa náà sì máa kọ́ tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa àpẹẹrẹ Jésù? (b) Kí ni Jésù ṣe nípa ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà, kí ló sì máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?
5 Àmọ́ o, àwọn oníṣòwò yẹn tún pa dà sínú tẹ́ńpìlì náà. Torí ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ìyẹn, Jésù tún bá wọn wí lórí ọ̀rọ̀ kan náà, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí ńṣe ni Jésù dìídì lo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fúnra ẹ̀ sọ láti fi bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó sọ ilé Rẹ̀ di “ihò àwọn olè.” (Jeremáyà 7:11; Mátíù 21:13) Nígbà tí Jésù rí bí wọ́n ṣe ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ àti bí wọ́n ṣe sọ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run di ibi àìmọ́, ó ká a lára bó ṣe ń ká Baba rẹ̀ lára. Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Jésù náà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo bíi ti Bàbá rẹ̀. Ó ṣe tán, àìmọye ọdún ló ti fi kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Baba rẹ̀ ọ̀run. Wọ́n ṣáà máa ń sọ pé, “Ẹní bíni làá jọ.” Torí náà, ohun tó dáa jù lọ tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ onídàájọ́ òdodo ni pé ká ronú jinlẹ̀ nípa àpẹẹrẹ Jésù Kristi.—Jòhánù 14:9, 10.
6 Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà wà níbẹ̀ nígbà tí Sátánì pe Jèhófà Ọlọ́run ní òpùrọ́, tó sì tún sọ pé Jèhófà ò lè ṣàkóso lọ́nà tó tọ́. Ẹ ò rí i pé ìbanilórúkọjẹ́ gbáà nìyẹn! Ọmọ yìí tún gbọ́ nígbà tí Sátánì sọ pé torí ohun táwọn èèyàn máa rí gbà lọ́wọ́ Jèhófà ni wọ́n ṣe ń sìn ín, kì í ṣe torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Torí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, ó dájú pé inú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an nígbà tí Sátánì fẹ̀sùn èké kan Bàbá rẹ̀. Àmọ́, inú ẹ̀ dùn gan-an nígbà tó mọ̀ pé Jèhófà máa lo òun láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan, ìyẹn láti jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé òpùrọ́ ni Sátánì! (2 Kọ́ríńtì 1:20) Báwo ló ṣe máa ṣe é?
7 Ní Orí 14, a kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jésù Kristi ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, tó sì fi hàn pé irọ́ ni Sátánì pa nígbà tó sọ pé kò sẹ́ni tó lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀. Ohun tí Jésù ṣe yẹn ló máa pa Sátánì lẹ́nu mọ́ títí láé, torí ó máa mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ Jèhófà, á sì jẹ́ kó ṣe kedere pé àkóso Jèhófà ló dáa jù lọ. Jésù ni Olórí Aṣojú Jèhófà, torí náà ó máa fìdí ìdájọ́ òdodo Jèhófà múlẹ̀ láyé àti lọ́run. (Ìṣe 5:31) Ó ṣe tán nígbà tó wà láyé, gbogbo ohun tó ṣe àti ohun tó fi kọ́ni bá ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run mu. Ohun tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ ni pé: “Màá fi ẹ̀mí mi sára rẹ̀, ó sì máa jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo ṣe kedere sí àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 12:18) Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe ṣẹ sí Jésù lára?
Jésù Jẹ́ Kí “Ìdájọ́ Òdodo Ṣe Kedere”
8-10. (a) Báwo làwọn òfin táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù gbé kalẹ̀ ṣe mú káwọn èèyàn kórìíra àwọn tí kì í ṣe Júù, kí wọ́n sì tàbùkù sí àwọn obìnrin? (b) Báwo làwọn òfin táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù gbé kalẹ̀ ṣe mú kó nira fáwọn èèyàn láti pa òfin tí Jèhófà ṣe nípa Sábáàtì mọ́?
8 Jésù fẹ́ràn Òfin Jèhófà, ó sì máa ń pa á mọ́. Àmọ́ ní tàwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé Jésù, dípò tí wọ́n á fi jẹ́ káwọn èèyàn lóye Òfin náà, ṣe ni wọ́n ń túmọ̀ ẹ̀ sódì. Torí náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! . . . Ẹ ò ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin sí, ìyẹn ìdájọ́ òdodo, àánú àti òtítọ́.” (Mátíù 23:23) Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí ló yẹ kó máa kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Ọlọ́run, àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe jẹ́ kó nira fáwọn èèyàn láti mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí. Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà ń ṣe bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan.
9 Jèhófà sọ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. (1 Àwọn Ọba 11:1, 2) Àmọ́, aláṣejù làwọn kan lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn, ṣe ni wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n kórìíra àwọn tí kì í ṣe Júù. Kódà, nínú ìwé kan táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ṣe, wọ́n pàṣẹ fáwọn èèyàn pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi àwọn ẹran ọ̀sìn yín sílẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn kèfèrí torí wọ́n lè bá ẹranko náà lò pọ̀.” Kò dáa rárá bí wọ́n ṣe ń ṣẹ̀tanú sí àwọn tí kì í ṣe Júù yìí, ó sì lòdì sí ohun tí Jèhófà kọ́ wọn nínú Òfin Mósè. (Léfítíkù 19:34) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn òfin àtọwọ́dá míì tí wọ́n gbé kalẹ̀ tàbùkù sí àwọn obìnrin. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn òfin yẹn sọ pé ìyàwó ò gbọ́dọ̀ rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ ẹ̀, ńṣe ni kó máa rìn lẹ́yìn ẹ̀. Kódà, wọ́n kìlọ̀ fáwọn ọkùnrin pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá obìnrin sọ̀rọ̀ níta gbangba, títí kan ìyàwó wọn pàápàá. Bákan náà, wọn ò gbà káwọn obìnrin jẹ́ ẹlẹ́rìí ọ̀rọ̀ nílé ẹjọ́ bí wọn ò ṣe gbà káwọn ẹrú jẹ́rìí nílé ẹjọ́. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn tiẹ̀ máa ń gba àdúrà kan tí wọ́n fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé àwọn kì í ṣe obìnrin.
10 Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn gbé oríṣiríṣi òfin kalẹ̀, ìyẹn sì mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fún wọn lófin. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí òfin Sábáàtì sọ ò ju pé àwọn èèyàn ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sábáàtì, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló yẹ kí wọ́n ya ọjọ́ náà sọ́tọ̀ láti fi jọ́sìn Jèhófà, kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan táá mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ ọn, kí wọ́n sì sinmi. Àmọ́, àwọn Farisí mú kó nira fáwọn èèyàn láti máa pa òfin náà mọ́. Wọ́n gbà pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí òfin náà pè ní “iṣẹ́.” Wọ́n wá pín ohun tí wọ́n kà sí iṣẹ́ sí ìsọ̀rí mọ́kàndínlógójì (39), bí àpẹẹrẹ iṣẹ́ ìkórè àti iṣẹ́ ọdẹ. Ohun tí wọ́n ṣe yìí mú káwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe àtèyí tí kò yẹ kí wọ́n ṣe lọ́jọ́ Sábáàtì. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá pa eégbọn lọ́jọ́ Sábáàtì, ṣé a lè sọ pé ńṣe lẹni náà ṣọdẹ? Téèyàn bá fọwọ́ já hóró ọkà mélòó kan sẹ́nu tó sì ń jẹ ẹ́ bó ṣe ń rìn lọ, ṣéyẹn fi hàn pé ó ti kórè? Téèyàn bá mú ẹni tó ń ṣàìsàn lára dá, ṣéyẹn túmọ̀ sí pé ó ti ṣiṣẹ́? Káwọn aṣáájú ẹ̀sìn lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ṣe ni wọ́n tún ṣe àwọn òfin jàn-àn-ràn jan-an-ran tó ṣòro láti pa mọ́.
11, 12. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé kì í ṣe òótọ́ làwọn Farisí fi ń kọ́ni?
11 Ọ̀pọ̀ èèyàn làwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ti ṣì lọ́nà, àmọ́ báwo ni Jésù ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí? Ńṣe ló fìgboyà ta ko àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn. Ó jẹ́ káwọn èèyàn rí i nínú ìwà ẹ̀ àti ohun tó ń kọ́ni pé òótọ́ kọ́ làwọn aṣáájú ẹ̀sìn náà fi ń kọ́ni. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jésù kọ́ni. Ó bẹnu àtẹ́ lu oríṣiríṣi òfin táwọn aṣáájú ẹ̀sìn gbé kalẹ̀, ó ní: “Ẹ̀ ń . . . fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín, tí ẹ fi lé àwọn èèyàn lọ́wọ́, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ.”—Máàkù 7:13.
12 Jésù fìtara kọ́ àwọn èèyàn pé èrò táwọn Farisí ní nípa òfin Sábáàtì kò tọ̀nà rárá, àti pé wọn kò lóye ìdí tí Jèhófà fi fún wọn ní òfin náà. Torí pé Jésù ni Mèsáyà, ó sọ fún wọn pé òun ni “Olúwa Sábáàtì,” òun sì lẹ́tọ̀ọ́ láti woni sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. (Mátíù 12:8) Kí Jésù lè mú kó dá wọn lójú pé òótọ́ lòun sọ, ó mú àwọn aláìsàn lára dá lójú ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́jọ́ Sábáàtì. (Lúùkù 6:7-10) Èyí sì jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣe kárí ayé lọ́jọ́ iwájú nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀. Ẹgbẹ̀rún Ọdún yẹn ló máa jẹ́ Sábáàtì tó ga jù lọ, torí pé ìgbà yẹn gangan làwọn olóòótọ́ máa sinmi, tí wọ́n sì máa rí ìtura kúrò nínú gbogbo wàhálà ti ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti mú bá wọn láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.
13. Òfin wo ni Jésù gbé kalẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, báwo ló sì ṣe yàtọ̀ sí Òfin Mósè?
13 Jésù tún jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí nípa bó ṣe gbé òfin tuntun kan kalẹ̀, ìyẹn “òfin Kristi.” Òfin náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́yìn tí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé. (Gálátíà 6:2) Òfin tuntun yìí yàtọ̀ sí Òfin Mósè ní ti pé ìlànà ló pọ̀ jù nínú ẹ̀, kì í ṣe àṣẹ. Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò sí àṣẹ nínú òfin tuntun yìí. Bí àpẹẹrẹ, Jésù pe ọ̀kan lára òfin náà ní “àṣẹ tuntun.” Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. (Jòhánù 13:34, 35) Irú ìfẹ́ yìí ló máa jẹ́ ká dá gbogbo àwọn tó bá ń tẹ̀ lé “òfin Kristi” mọ̀.
Jésù Máa Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo
14, 15. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun, kí sì nìdí tí èyí fi fi wá lọ́kàn balẹ̀?
14 Jésù tipasẹ ohun tó sọ àti ohun tó ṣe kọ́ àwọn èèyàn pé ó yẹ kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́. Gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé òun fúnra ẹ̀ ń tẹ̀ lé “òfin Kristi.” Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan mẹ́ta tó ṣe tó fi hàn pé ó mú kí ìdájọ́ òdodo ṣe kedere.
15 Lákọ̀ọ́kọ́, Jésù ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó má bàa rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti kíyè sí i pé ìgbéraga àti ìkọjá àyè ló sábà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn rẹ́ni jẹ. Àmọ́, Jésù ò ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́jọ́ kan, ọkùnrin kan wá bá Jésù, ó sọ fún un pé: “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kó pín ogún fún mi.” Kí wá ni Jésù sọ fún un? Ó sọ pé: “Ọkùnrin yìí, ta ló yàn mí ṣe adájọ́ tàbí alárinà láàárín ẹ̀yin méjèèjì?” (Lúùkù 12:13, 14) Kí ni ohun tó sọ yìí kọ́ wa nípa Jésù? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé làákàyè àti ọgbọ́n Jésù ju ti ẹnikẹ́ni lọ, àṣẹ tí Jèhófà fún un sì ju ti ẹnikẹ́ni lọ, kò ṣèpinnu fún ọkùnrin yẹn torí pé Ọlọ́run ò fún un láṣẹ láti dá sí ọ̀rọ̀ náà. Jésù mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, kódà ni gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tó fi wà lọ́run kó tó wá sáyé, kò kọjá àyè ẹ̀ rí. (Júùdù 9) Onírẹ̀lẹ̀ ni, ó sì gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o!
16, 17. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé onídàájọ́ òdodo lòun nínú bó ṣe wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run? (b) Kí ni ọ̀nà kẹta tí Jésù gbà fi hàn pé òun jẹ́ onídàájọ́ òdodo? Ṣàlàyé.
16 Ìkejì, Jésù fi hàn pé onídàájọ́ òdodo lòun nínú bó ṣe wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kì í ṣe ojúsàájú, gbogbo èèyàn ló wàásù fún, ì báà jẹ́ olówó tàbí tálákà. Òdìkejì ohun tí Jésù ṣe làwọn Farisí ń ṣe ní tiwọn, wọ́n gbà pé èèyàn lásán làwọn tálákà, wọ́n sì máa ń pè wọ́n ní ʽam-ha·ʼaʹrets, tó túmọ̀ sí “àwọn ẹni ilẹ̀.” Jésù fìgboyà sọ fún wọn pé ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn ò dáa. Jésù wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn, ó bá wọn jẹun, ó pèsè oúnjẹ fún wọn, ó mú wọn lára dá, kódà ó jí àwọn tó ti kú dìde. Àwọn nǹkan tó ṣe yìí àti ọ̀nà tó gbà ṣe é fi hàn pé ó ń fara wé Jèhófà Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo, ẹni tó fẹ́ gba “onírúurú èèyàn” là.c—1 Tímótì 2:4.
17 Ọ̀nà kẹta tí Jésù gbà fi hàn pé òun jẹ́ onídàájọ́ òdodo ni bó ṣe máa ń ṣàánú àwọn èèyàn látọkàn wá. Ó gbé ìgbésẹ̀ láti ran àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. (Mátíù 9:11-13) Gbogbo ìgbà ló máa ń wá bó ṣe máa ṣèrànwọ́ fáwọn tí kò lẹ́ni tó máa gbèjà wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jésù ò fara mọ́ ohun táwọn Farisí ń kọ́ni pé ńṣe ló yẹ kéèyàn kórìíra àwọn tí kì í ṣe Júù àti pé wọn ò ṣeé fọkàn tán. Jésù máa ń ṣàánú àwọn tí kì í ṣe Júù, ó sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù ni Jèhófà dìídì rán an sí. Bí àpẹẹrẹ, ó gbà láti wo ìránṣẹ́ ọ̀gágun Róòmù kan sàn, ó ní: “Mi ò tíì rí ẹnì kankan ní Ísírẹ́lì tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tó báyìí.”—Mátíù 8:5-13.
18, 19. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà buyì kún àwọn obìnrin? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe jẹ́ ká rí i pé èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà kó tó lè máa ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu?
18 Bákan náà, dípò tí Jésù á fi fara mọ́ ojú táwọn èèyàn ìgbà yẹn fi ń wo àwọn obìnrin, ṣe ló fìgboyà ṣe ohun tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, láyé ìgbà yẹn ojú kan náà làwọn Júù fi ń wo àwọn tí kì í ṣe Júù àtàwọn obìnrin tó jẹ́ ará Samáríà, ńṣe ni wọ́n kà wọ́n sí aláìmọ́. Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí Jésù tijú láti wàásù fún obìnrin ará Samáríà tó rí létí kànga kan nílùú Síkárì. Kódà, obìnrin yìí ni Jésù kọ́kọ́ sọ fún ní tààràtà pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Jòhánù 4:6, 25, 26) Àwọn Farisí sọ pé kò yẹ kí wọ́n kọ́ àwọn obìnrin lófin Ọlọ́run, àmọ́ Jésù máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun rẹ̀ láti kọ́ àwọn obìnrin. (Lúùkù 10:38-42) Bákan náà, nínú àṣà àwọn Júù, tí obìnrin bá ṣe ẹlẹ́rìí lórí ọ̀rọ̀ kan, wọn kì í gbà pé òótọ́ lohun tó sọ. Àmọ́ Jésù fún àwọn obìnrin kan láǹfààní láti kọ́kọ́ rí òun lẹ́yìn tó jíǹde, èyí sì buyì kún wọn gan-an. Kódà, Jésù tún sọ fáwọn obìnrin yẹn pé kí wọ́n lọ ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì náà fáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun tó jẹ́ ọkùnrin!—Mátíù 28:1-10.
19 Ká sòótọ́, Jésù jẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí gan-an. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé ẹ̀mí ẹ̀ máa ń wà nínú ewu tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká rí i pé èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà kó tó lè máa ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè é ní “Kìnnìún ẹ̀yà Júdà.” (Ìfihàn 5:5) Rántí pé ẹranko tó nígboyà ni kìnnìún, ó sì máa ń dúró fún ìdájọ́ òdodo. Láìpẹ́, Jésù máa ṣe ohun tó ju èyí tó ṣe nígbà yẹn lọ, ó máa túbọ̀ “fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ ní ayé.”—Àìsáyà 42:4.
Mèsáyà Ọba “Fìdí Ìdájọ́ Òdodo Múlẹ̀ ní Ayé”
20, 21. Lóde òní, báwo ni Jésù Ọba Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń mú kí ìdájọ́ òdodo wà kárí ayé àti nínú ìjọ Kristẹni?
20 Látìgbà tí Jésù ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914, ló ti ń ṣe ohun táá mú kí ìdájọ́ òdodo wà kárí ayé. Àwọn nǹkan wo ló ti ṣe? Ó ti ṣe àwọn nǹkan tó mú kí àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nínú Mátíù 24:14 ṣẹ. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó wà lórí ilẹ̀ ayé ti kọ́ àwọn èèyàn láti onírúurú ilẹ̀ ní òtítọ́ nípa Ìjọba Jèhófà. Bíi ti Jésù, àwọn náà ń wàásù fún gbogbo èèyàn lọ́mọdé lágbà, tọkùnrin tobìnrin, olówó àti tálákà, wọ́n jẹ́ kí gbogbo èèyàn láǹfààní láti mọ Jèhófà, Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo.
21 Jésù tún ń rí sí i pé ìdájọ́ òdodo wà nínú ìjọ Kristẹni. Òun ni Orí ìjọ, bó sì ṣe wà lásọtẹ́lẹ̀, ó ń pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn,” ìyẹn àwọn Kristẹni alàgbà tí wọ́n ń múpò iwájú nínú ìjọ. (Éfésù 4:8-12) Gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ló ṣeyebíye sí Jésù. Torí náà ó fẹ́ káwọn alàgbà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun, kí wọ́n sì máa bójú tó wọn lọ́nà tó tọ́ láìka ipò wọn sí, yálà wọ́n jẹ́ olówó tàbí tálákà.
22. Báwo ni ìwà ìrẹ́jẹ tó ń pọ̀ sí i láyé yìí ṣe rí lára Jèhófà, kí ló sì sọ pé Ọmọ òun máa ṣe sí i?
22 Láìpẹ́, Jésù máa fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ, ó sì máa mú kí ìdájọ́ òdodo fìdí múlẹ̀ kárí ayé lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ńṣe ni ìwà ìrẹ́jẹ túbọ̀ ń pọ̀ sí i nínú ayé burúkú yìí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọmọdé ló ti kú torí pé wọn ò rí oúnjẹ tó tó jẹ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ńṣe làwọn orílẹ̀-èdè ń ná owó ńlá láti fi kó ohun ìjà jọ, táwọn èèyàn kan sì ń fowó ṣòfò torí kí wọ́n lè tẹ́ ara wọn lọ́rùn. Bákan náà, ká sọ pé nǹkan rí bó ṣe yẹ kó rí nílùú, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń kú lọ́dọọdún ni ò ní kú. Gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù láyé yìí ń múnú bí Jèhófà gan-an. Torí náà, ó ti yan Ọmọ rẹ̀ pé kó bá gbogbo ètò búburú ayé yìí jagun kó lè fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ títí láé.—Ìfihàn 16:14, 16; 19:11-15.
23. Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, báwo ni Kristi á ṣe máa ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu títí láé?
23 Àmọ́ o, ìdájọ́ òdodo Jèhófà kọjá pé kó kàn pa àwọn èèyàn burúkú run. Ó tún ti yan Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” pé kó ṣàkóso. Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, àkóso Jésù máa mú kí àlàáfíà wà kárí ayé, ó sì máa ṣe “ìdájọ́ tí ó tọ́” nígbà tó bá ń jọba. (Àìsáyà 9:6, 7) Inú Jésù máa dùn gan-an láti fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ tó ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn jìyà. Títí láé ni Jésù fi máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, táá sì máa ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo Jèhófà mu. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo Jèhófà ní báyìí. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.
a Bí Jésù ṣe bínú lọ́nà òdodo yìí, fi hàn pé ó jọ Jèhófà, ẹni tó “ṣe tán láti bínú” nítorí gbogbo ìwà ibi. (Náhúmù 1:2) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ oníwàkiwà pé wọ́n ti sọ ilé òun di “ihò tí àwọn olè ń fara pa mọ́ sí,” ó ní: “Ìbínú mi àti ìrunú mi yóò dà sórí ibí yìí.”—Jeremáyà 7:11, 20.
b Ìwé kan tó ń sọ ìtàn àwọn Júù sọ pé lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà àwọn èèyàn kan fẹ̀hónú hàn torí pé iye tí wọ́n ń ta àdàbà nínú tẹ́ńpìlì ti pọ̀ jù. Ọjọ́ yẹn gangan ni wọ́n dín iye tí wọ́n ń tà á kù. Bí àpẹẹrẹ, ká ní wọ́n ń ta ọjà kan ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) náírà, wọ́n sọ ọ́ di náírà mẹ́wàá! Ta ló ń gba èyí tó pọ̀ jù nínú èrè táwọn oníṣòwò ń rí lórí owó ẹran tí wọ́n ń tà nínú tẹ́ńpìlì yẹn? Àwọn òpìtàn kan sọ pé agbo ilé Ánásì Àlùfáà Àgbà ló ni àwọn ọjà tí wọ́n ń tà nínú tẹ́ńpìlì yẹn, wọ́n sì gbà pé èyí ló sọ agbo ilé àlùfáà náà di ọlọ́rọ̀.—Jòhánù 18:13.
c Àwọn Farisí sọ pé “ẹni ègún” làwọn tálákà tí kò mọ Òfin. (Jòhánù 7:49) Wọ́n ní ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, kò gbọ́dọ̀ bá wọn dòwò pọ̀, kò gbọ́dọ̀ bá wọn jẹun tàbí kó bá wọn gbàdúrà. Wọ́n ní tẹ́nì kan bá gbà kí ọmọbìnrin rẹ̀ fẹ́ ọ̀kan lára wọn, ohun tẹ́ni náà ṣe burú ju pé kó gbé ọmọ ẹ̀ fún ẹranko láti pa á jẹ. Wọ́n tiẹ̀ tún gbà pé kò ní sí àjíǹde fáwọn tálákà tí kò mọ Òfin.
-
-
Máa “Ṣe Ìdájọ́ Òdodo” Bó O Ṣe Ń Bá Ọlọ́run RìnSún Mọ́ Jèhófà
-
-
ORÍ 16
Máa “Ṣe Ìdájọ́ Òdodo” Bó O Ṣe Ń Bá Ọlọ́run Rìn
1-3. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà? (b) Kí ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe ká lè fi hàn pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa?
FOJÚ inú wò ó pé o wà nínú ọkọ̀ òkun kan tó ń rì lójú agbami. O ti rò ó pin pé kò sọ́nà àbáyọ kankan fún ẹ mọ́, àmọ́ ṣàdédé ni ẹnì kan dé tó sì fà ẹ́ wọnú ọkọ̀ míì. Ó dájú pé ọkàn ẹ máa balẹ̀ gan-an bí ẹni náà ṣe fà ẹ́ kúrò nínú omi tó sì tún sọ pé: “O ti bọ́ báyìí, kò séwu mọ́”! Báwo ni nǹkan tẹ́ni náà ṣe fún ẹ ṣe máa rí lára ẹ? Ó dájú pé o máa mọyì ẹ̀ gan-an, torí pé ńṣe lẹni náà gba ẹ̀mí ẹ là.
2 Àpèjúwe yìí jẹ́ ká lóye ohun tí Jèhófà ṣe fún wa. Ó sì yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ torí òun ló fún wa ní ìràpadà tó mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ó dá wa lójú pé tá a bá ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà tó ṣeyebíye yẹn, Jèhófà máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, a sì máa wà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú. (1 Jòhánù 1:7; 4:9) Ní Orí 14 ìwé yìí, a rí i pé ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa àti pé òun jẹ́ onídàájọ́ òdodo ni bó ṣe fún wa ní ìràpadà. Kí la lè ṣe táá jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa?
3 Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ ohun tó fẹ́ ká ṣe. Jèhófà lo wòlíì Míkà láti jẹ́ ká mọ ohun tóun fẹ́. Ó sọ pé: “Ó ti sọ ohun tó dára fún ọ, ìwọ ọmọ aráyé. Kí sì ni Jèhófà fẹ́ kí o ṣe? Bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o mọyì jíjẹ́ adúróṣinṣin, kí o sì mọ̀wọ̀n ara rẹ bí o ṣe ń bá Ọlọ́run rẹ rìn!” (Míkà 6:8) Torí náà, ọ̀kan lára ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe ni pé ká “ṣe ìdájọ́ òdodo.” Báwo la ṣe lè ṣe é?
Máa Wá “Òdodo Tòótọ́”
4. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń retí pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo òun?
4 Jèhófà ń retí pé ká máa tẹ̀ lé ìlànà òun nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. A mọ̀ pé àwọn ìlànà Jèhófà jẹ́ òdodo, wọ́n sì bá ìdájọ́ òdodo mu, torí náà tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀ èyí á fi hàn pé àwa náà nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo. Àìsáyà 1:17 sọ pé: “Ẹ kọ́ bí ẹ ṣe máa ṣe rere, ẹ wá ìdájọ́ òdodo.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún sọ pé ká “wá òdodo.” (Sefanáyà 2:3) Bákan náà, ó rọ̀ wá pé ká “gbé ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ.” (Éfésù 4:24) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà, àá máa yẹra fún ìwà ipá, ìwà àìmọ́ àti ìṣekúṣe, torí pé irú àwọn ìwà yìí lòdì sí ìlànà Jèhófà.—Sáàmù 11:5; Éfésù 5:3-5.
5, 6. (a) Kí nìdí tí kò fi nira láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà? (b) Kí ni Bíbélì sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ máa wá òdodo a gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ láìdáwọ́ dúró?
5 Ṣó nira láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà? Rárá o. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lẹnì kan nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò ní ṣòro fún un láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wa, a sì mọyì àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀, gbogbo ìgbà ló máa ń wù wá pé ká ṣe ohun táá múnú rẹ̀ dùn. (1 Jòhánù 5:3) Rántí pé Jèhófà “nífẹ̀ẹ́ àwọn iṣẹ́ òdodo.” (Sáàmù 11:7) Tá a bá sì fẹ́ fara wé Jèhófà, a ní láti nífẹ̀ẹ́ ohun tó nífẹ̀ẹ́ ká sì kórìíra ohun tó kórìíra.—Sáàmù 97:10.
6 Torí pé a jẹ́ aláìpé, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn fún wa láti ṣe ohun tó tọ́. Ìdí nìyẹn tá a fi gbọ́dọ̀ bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ká sì gbé tuntun wọ̀. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà tuntun yìí, ó ní ‘à ń sọ ọ́ di tuntun’ nípasẹ̀ ìmọ̀ tó péye. (Kólósè 3:9, 10) Gbólóhùn náà, ‘à ń sọ ọ́ di tuntun,’ jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ gbé ìwà tuntun wọ̀, kì í ṣe nǹkan tá a máa ṣe lẹ́ẹ̀kan tá a sì máa dáwọ́ dúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làá máa ṣe é nìṣó, èyí sì gba ìsapá. Àmọ́ bó ti wù ká sapá tó, a ṣì lè ṣàṣìṣe nínú èrò, ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe wa torí pé aláìpé ni wá.—Róòmù 7:14-20; Jémíìsì 3:2.
7. Bá a ṣe ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ́, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ṣàṣìṣe?
7 Bá a ṣe ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ́, a máa ń ṣàṣìṣe nígbà míì. Kí ló wá yẹ ká ṣe? Òótọ́ ni pé kò yẹ ká máa wí àwíjàre tá a bá ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀, ká wá máa rò pé àwọn àṣìṣe wa ti pọ̀ jù, torí náà a ò yẹ lẹ́ni tó ń sin Jèhófà. Ẹ rántí pé Bàbá wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ti ṣètò pé káwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn pa dà rí ojú rere òun. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Mò ń kọ àwọn nǹkan yìí sí yín kí ẹ má bàa dẹ́ṣẹ̀.” Àmọ́, ó tún fi kún un pé: “Síbẹ̀, tí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ [torí àìpé tá a jogún], a ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi.” (1 Jòhánù 2:1) Bẹ́ẹ̀ ni, bá a tiẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹbọ ìràpadà tí Jèhófà pèsè nípasẹ̀ Jésù ti mú ká lè máa jọ́sìn Jèhófà ní fàlàlà. Ṣé ìyẹn ò fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀? Ṣé kò sì mú kó wù ẹ́ pé kó o máa sa gbogbo ipá rẹ kó o lè máa ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn?
Ìhìn Rere Tá À Ń Wàásù Fi Hàn Pé Onídàájọ́ Òdodo ni Ọlọ́run
8, 9. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe fi hàn pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà?
8 Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà máa ṣèdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà ni pé ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ṣe fi hàn pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà?
9 Jèhófà ò ní dédé pa ayé burúkú yìí run láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ kìlọ̀ fáwọn èèyàn. Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò òpin, ó sọ pé: “A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10; Mátíù 24:3) Bí Jésù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “kọ́kọ́” jẹ́ ká rí i pé àwọn nǹkan míì máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ìwàásù ìhìn rere náà bá ti kárí ayé. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ ni Bíbélì pè ní ìpọ́njú ńlá, ìyẹn ìgbà tí Ọlọ́run máa pa àwọn èèyàn búburú run, táá sì mú kí ayé tuntun dé níbi tí òdodo á máa gbé. (Mátíù 24:14, 21, 22) Ó dájú pé kò ṣẹ́ni tó máa sọ pé ńṣe ni Jèhófà hùwà tí ò dáa sáwọn èèyàn burúkú nígbà yẹn. Jèhófà ń lo iṣẹ́ ìwàásù láti kìlọ̀ fún wọn ní báyìí, torí ó fẹ́ kí wọ́n yí pa dà kí wọ́n lè rí ìgbàlà.—Jónà 3:1-10.
10, 11. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo Jèhófà?
10 Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ṣe fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo Jèhófà? Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Ṣé o rántí àpèjúwe tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí nípa ọkọ̀ òkun tó ń rì, tẹ́nì kan wá fà ẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀? Lẹ́yìn tẹ́ni náà gbé ẹ sínú ọkọ̀ míì, ó dájú pé wàá fẹ́ ran àwọn tó ṣì wà nínú omi yẹn lọ́wọ́. Bọ́rọ̀ àwọn èèyàn tó wà nínú ayé burúkú yìí ṣe rí nìyẹn, ńṣe ni wọ́n dà bí ẹni tó ń rì sínú odò. Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa pa run. Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Àmọ́, ní báyìí tí Jèhófà ṣì ń mú sùúrù fún wọn, ó yẹ ká sa gbogbo ipá wa láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè “ronú pìwà dà,” torí ìyẹn láá jẹ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà.—2 Pétérù 3:9.
11 Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé à ń fara wé Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo ni pé ká máa wàásù fún gbogbo èèyàn, torí ìyẹn ló máa fi hàn pé a kì í ṣe ojúsàájú. Rántí pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Ìṣe 10:34, 35) Tá a bá fẹ́ jẹ́ onídàájọ́ òdodo bíi ti Ọlọ́run, a ò gbọ́dọ̀ máa ṣe ojúsàájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa wàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn láìka ibi tí wọ́n ti wá sí, ojú táwọn èèyàn fi ń wò wọ́n, tàbí bóyá olówó ni wọ́n tàbí tálákà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa fún gbogbo èèyàn láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere náà, kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti rí ìgbàlà.—Róòmù 10:11-13.
Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Síra Wa
12, 13. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká tètè máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́? (b) Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ká “yéé dáni lẹ́jọ́” àti pé ká “yéé dáni lẹ́bi”? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
12 Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà fi hàn pé à ń ṣèdájọ́ òdodo ni pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe ń ṣe sí wa. A sábà máa ń ríbi táwọn èèyàn kù sí, torí náà ó máa ń yá wa lára láti dá wọn lẹ́jọ́ tàbí ṣàríwísí wọn. Àmọ́, ó dájú pé kò sẹ́ni tó máa fẹ́ kí Jèhófà máa ṣàríwísí òun ní gbogbo ìgbà, tàbí kó máa dá òun lẹ́jọ́. Jèhófà kì í ṣe bẹ́ẹ̀ sí wa rárá. Onísáàmù kan sọ pé: “Jáà, tó bá jẹ́ pé àṣìṣe lò ń wò, Jèhófà, ta ló lè dúró?” (Sáàmù 130:3) A mà dúpẹ́ o pé onídàájọ́ òdodo àti aláàánú ni Ọlọ́run wa, torí ó máa ń gbójú fo àwọn àṣìṣe wa! (Sáàmù 103:8-10) Báwo ló wá yẹ káwa náà máa ṣe sáwọn èèyàn?
13 Tẹ́nì kan bá ṣàṣìṣe, a máa fi hàn pé a jẹ́ aláàánú àti onídàájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà tá a bá gbójú fo ohun tẹ́ni náà ṣe, tá ò sì tètè dá a lẹ́jọ́, ní pàtàkì tí ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ò bá kàn wá, tàbí tí ò tó nǹkan. Nínú Ìwàásù Orí Òkè, Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.” (Mátíù 7:1) Nínú ìwé Ìhìn Rere Lúùkù, Jésù fi kún un pé: “Ẹ yéé dáni lẹ́bi, ó sì dájú pé a ò ní dá yín lẹ́bi.”a (Lúùkù 6:37) Jésù mọ̀ pé àwa èèyàn aláìpé sábà máa ń ṣàríwísí ara wa tàbí dá ara wa lẹ́bi. Torí náà, tí èyíkéyìí lára àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó fẹ́ kí wọ́n jáwọ́.
Tá a bá ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn láìṣe ojúsàájú, ńṣe là ń fara wé Jèhófà tó jẹ́ onídàájọ́ òdodo
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé ká “yéé dáni lẹ́jọ́”?
14 Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé ká “yéé dáni lẹ́jọ́”? Ìdí kan ni pé a ò lẹ́tọ̀ọ́ láti dáni lẹ́jọ́. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jémíìsì sọ pé: “Ẹnì kan ṣoṣo ni Afúnnilófin àti Onídàájọ́ wa,” ìyẹn Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí Jémíìsì fi wá béèrè pé: “Ta ni ọ́ tí o fi ń dá ọmọnìkejì rẹ lẹ́jọ́?” (Jémíìsì 4:12; Róòmù 14:1-4) Yàtọ̀ síyẹn, torí pé a jẹ́ aláìpé, a kì í sábà ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́. Lára ìwà àti ìṣe tí kì í jẹ́ ká ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́ ni ẹ̀tanú, ìkanra pé ẹnì kan rí wa fín, owú àti òdodo àṣelékè. Ohun kan tún wà tó yẹ ká fi sọ́kàn tí kò ní jẹ́ ká máa ṣàríwísí àwọn èèyàn, ìyẹn ni pé a ò lè rí ọkàn wọn, a ò sì lè mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn. Torí náà, ṣó wá yẹ ká gbà pé èrò tí kò tọ́ ló wà lọ́kàn àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà tàbí pé wọn ò ṣe tó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn? Rárá o. Ńṣe ló yẹ ká máa fara wé Jèhófà, ká máa wá ibi táwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin dáa sí, dípò ká máa tanná wá àṣìṣe wọn kiri!
15. Irú ìwà àti ìṣe wo la ò gbọ́dọ̀ bá lọ́wọ́ àwọn olùjọsìn Ọlọ́run, kí sì nìdí?
15 Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn ará ilé wa? Inú ìdílé ló yẹ kó jẹ́ ibi tó tura jù, àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé àwọn tó wà nínú ìdílé ló máa ń hùwà ìkà síra wọn jù. A sábà máa ń gbọ́ nípa àwọn ọkọ, aya, tàbí òbí tí wọ́n máa ń bú àwọn ará ilé wọn, tí wọ́n máa ń ṣépè fún wọn, tí wọ́n sì máa ń lù wọ́n. Àmọ́, kò yẹ káwọn olùjọsìn Jèhófà máa sọ̀rọ̀ burúkú síra wọn, tàbí kí wọ́n máa hùwà ìkà síra wọn. (Éfésù 4:29, 31; 5:33; 6:4) Ó yẹ káwọn tó wà nínú ìdílé náà máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé ká “yéé dáni lẹ́jọ́” ká sì “yéé dáni lẹ́bi.” Rántí pé lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣèdájọ́ òdodo ni pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa. Ọlọ́run wa kì í hùwà ìkà sí wa, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń fi “ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an” hàn sáwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Jémíìsì 5:11) Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà yìí!
Àwọn Alàgbà Ń Ṣe “Ìdájọ́ Òdodo”
16, 17. (a) Kí ni Jèhófà ń retí pé káwọn alàgbà máa ṣe? (b) Kí ló yẹ káwọn alàgbà ṣe tí ẹnì kan tó hùwà àìtọ́ ò bá ronú pìwà dà, kí sì nìdí?
16 Gbogbo wa ni Jèhófà ń retí pé ká máa ṣe ìdájọ́ òdodo, àmọ́ ní pàtàkì ọ̀rọ̀ náà kan àwọn alàgbà. Kíyè sí ohun tí Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa “àwọn ìjòyè,” tàbí àwọn alàgbà, ó ní: “Wò ó! Ọba kan máa jẹ fún òdodo, àwọn ìjòyè sì máa ṣàkóso fún ìdájọ́ òdodo.” (Àìsáyà 32:1) Èyí fi hàn pé Jèhófà retí pé káwọn alàgbà jẹ́ onídàájọ́ òdodo. Ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ wọn?
17 Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí mọ̀ pé táwọn bá fẹ́ jẹ́ onídàájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, àwọn gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́. Nígbà míì, ó máa ń pọn dandan pé káwọn alàgbà ṣèdájọ́ àwọn tó hùwà àìtọ́ tó burú gan-an. Tí wọ́n bá sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fi sọ́kàn pé Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n fàánú hàn nígbà tó bá yẹ. Torí náà, wọ́n máa ń gbìyànjú láti ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà. Àmọ́, kí ni wọ́n máa ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá ti sa gbogbo ipá wọn, síbẹ̀ tẹ́ni náà ò ronú pìwà dà? Bíbélì sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe táá fi hàn pé wọ́n ń ṣèdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, ó sọ pé: “Ẹ mú ẹni burúkú náà kúrò láàárín yín.” Ìyẹn túmọ̀ sí pé kí wọ́n yọ ẹni náà kúrò nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13; 2 Jòhánù 9-11) Inú àwọn alàgbà kì í dùn tí wọ́n bá fẹ́ yọ ẹnì kan kúrò nínú ìjọ, àmọ́ wọ́n mọ̀ pé ó yẹ káwọn ṣe bẹ́ẹ̀ kí ìwà ẹni náà má bàa kó bá àwọn tó kù nínú ìjọ, kí ìjọ sì lè wà ní mímọ́ tónítóní lójú Jèhófà. Síbẹ̀, wọ́n gbà pé lọ́jọ́ kan, ẹni tó hùwà àìtọ́ náà ṣì máa ronú pìwà dà, á sì pa dà sínú ìjọ.—Lúùkù 15:17, 18.
18. Kí làwọn alàgbà máa ń fi sọ́kàn tí wọ́n bá ń fúnni ní ìmọ̀ràn látinú Bíbélì?
18 Ọ̀nà míì táwọn alàgbà lè gbà fi hàn pé àwọn ń ṣèdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà ni pé kí wọ́n máa fúnni ní ìmọ̀ràn látinú Bíbélì nígbà tó bá yẹ. Àmọ́ o, kì í ṣe pé àwọn alàgbà ń wá àṣìṣe àwọn èèyàn kiri. Wọn kì í sì í wá bí wọ́n á ṣe máa báni wí ní gbogbo ìgbà. Àmọ́, tẹ́nì kan nínú ìjọ bá “ṣi ẹsẹ̀ gbé kó tó mọ̀,” ńṣe làwọn alàgbà máa “sapá láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tọ́ ẹni náà sọ́nà,” torí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run kì í le koko mọ́ni tó bá ń ṣèdájọ́. (Gálátíà 6:1) Àwọn alàgbà ò ní bú ẹni tó hùwà àìtọ́ náà tàbí kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ tí kò dáa sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ẹni náà, tí wọ́n á sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún un nímọ̀ràn kí ara lè tù ú. Kódà, tó bá gba pé káwọn alàgbà fún ẹnì kan nímọ̀ràn tó ṣe tààràtà kẹ́ni náà máa bàa kó sínú ìṣòro, wọ́n ṣì máa ń rántí pé àgùntàn Jèhófà lẹni náà.b (Lúùkù 15:7) Táwọn alàgbà bá ń fìfẹ́ hàn nígbà tí wọ́n bá ń fún ẹnì kan nímọ̀ràn tàbí bá a wí, wọ́n máa lè ran ẹni náà lọ́wọ́.
19. Àwọn ìpinnu wo ló máa ń pọn dandan káwọn alàgbà ṣe, kí ni wọ́n sì máa gbé yẹ̀ wò kí wọ́n tó ṣe àwọn ìpinnu náà?
19 Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn alàgbà ní láti ṣe àwọn ìpinnu tó kan àwọn ará nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alàgbà sábà máa ń pàdé pọ̀ láti wò ó bóyá àwọn arákùnrin kan nínú ìjọ ti tóótun láti di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àwọn alàgbà mọ̀ pé kò yẹ káwọn máa ṣojúsàájú. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu nípa àwọn tó tóótun láti di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ni wọ́n máa gbé yẹ̀ wò, kì í ṣe èrò tiwọn. Ìyẹn láá jẹ́ kí wọ́n ṣèpinnu “láìṣe ẹ̀tanú tàbí ojúsàájú.”—1 Tímótì 5:21.
20, 21. (a) Kí làwọn alàgbà máa ń gbìyànjú láti ṣe fáwọn ará, kí sì nìdí? (b) Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti ran “àwọn tó sorí kọ́” lọ́wọ́?
20 Àwọn alàgbà tún máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà láwọn ọ̀nà míì. Lẹ́yìn tí Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn alàgbà máa ṣiṣẹ́ “fún ìdájọ́ òdodo,” ó tún sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa dà bí ibi tó ṣeé fara pa mọ́ sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù, ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí omi tó ń ṣàn ní ilẹ̀ tí kò lómi, bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ tó gbẹ táútáú.” (Àìsáyà 32:2) Èyí fi hàn pé àwọn alàgbà máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tu àwọn ará nínú, kí wọ́n sì mú kára tù wọ́n.
21 Torí pé ìṣòro tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni pọ̀ nínú ayé, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló nílò ìṣírí. Ẹ̀yin alàgbà kí lẹ lè ṣe láti ran “àwọn tó sorí kọ́” lọ́wọ́? (1 Tẹsalóníkà 5:14) Ẹ fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, kẹ́ ẹ sì fọ̀rọ̀ wọn ro ara yín wò. (Jémíìsì 1:19) Wọ́n lè fẹ́ bá ẹnì kan tí wọ́n fọkàn tán sọ̀rọ̀ nípa àníyàn tó wà lọ́kàn wọn. (Òwe 12:25) Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà àtàwọn ará nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, wọ́n sì mọyì wọn. (1 Pétérù 1:22; 5:6, 7) Bákan náà, ẹ lè gbàdúrà pẹ̀lú wọn, kí ẹ sì tún máa rántí wọn nínú àdúrà yín. Tí alàgbà kan bá gbàdúrà látọkànwá pẹ̀lú ẹnì kan tó rẹ̀wẹ̀sì, ó dájú pé ará máa tu ẹni náà. (Jémíìsì 5:14, 15) Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, ó ń rí bẹ́ ẹ ṣe ń fìfẹ́ hàn, tẹ́ ẹ sì ń sapá láti ran àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì lọ́wọ́. Ó dájú pé kò ní gbàgbé gbogbo iṣẹ́ rere tẹ́ ẹ̀ ń ṣe.
Táwọn alàgbà bá ń fún àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì níṣìírí, ńṣe ni wọ́n ń gbé ìdájọ́ òdodo Jèhófà yọ
22. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ onídàájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, kí ló sì máa yọrí sí?
22 Ká sòótọ́, tá a bá ń ṣèdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, ńṣe làá túbọ̀ máa sún mọ́ ọn! Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, tá à ń wàásù fáwọn èèyàn kí wọ́n lè rí ìgbàlà, tá a sì ń wo ibi táwọn èèyàn dáa sí dípò ká máa ṣọ́ àṣìṣe wọn, ńṣe là ń gbé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run yọ. Ẹ̀yin alàgbà, tẹ́ ẹ bá ń ṣe ohun táá jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́, tẹ́ ẹ̀ ń fúnni ní ìmọ̀ràn tó ń gbéni ró látinú Ìwé Mímọ́, tẹ́ ò ṣe ojúsàájú nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣèpinnu, tẹ́ ẹ sì ń fún àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì níṣìírí, ńṣe lẹ̀ ń fi hàn pé ẹ jẹ́ onídàájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà. Ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn gan-an tó bá bojú wolẹ̀ látọ̀run tó sì rí àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti máa “ṣe ìdájọ́ òdodo” bí wọ́n ṣe ń bá Ọlọ́run wọn rìn!
a Nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan, wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí: “Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́,” àti “ẹ má ṣe dáni lẹ́bi.” Ohun téyìí túmọ̀ sí ni pé ká “má gbìyànjú láti dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ rárá” àti pé ká “má gbìyànjú láti dá àwọn èèyàn lẹ́bi rárá.” Àmọ́, ńṣe ni ọ̀rọ̀ táwọn tó kọ Ìwé Ìhìn Rere lò nínú ẹsẹ yìí ń sọ nípa ohun tẹ́nì kan ti ń ṣe tẹ́lẹ̀, tó sì ń bá a lọ láti máa ṣe. Torí náà, ńṣe ni Jésù ń sọ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé kí wọ́n yéé hu ìwà kan tí wọ́n ti ń hù tẹ́lẹ̀.
b Ní 2 Tímótì 4:2, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé nígbà míì ó lè pọn dandan káwọn alàgbà “báni wí,” kí wọ́n “fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà,” kí wọ́n sì “gbani níyànjú.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “gbani níyànjú” (pa·ra·ka·leʹo) tún lè túmọ̀ sí “láti fúnni ní ìṣírí.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì míì tó jọ ọ́ ni pa·raʹkle·tos, ó sì lè tọ́ka sí agbẹjọ́rò tó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nílé ẹjọ́. Torí náà, tẹ́nì kan bá tiẹ̀ ṣe ohun tí kò dáa, tó wá gba pé káwọn alàgbà bá a wí, wọ́n máa ń fi sọ́kàn pé ṣe ni wọ́n fẹ́ ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.
-