ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 23:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Bákan náà, kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Ìkórè* àwọn èso oko yín tó kọ́kọ́ pọ́n, èyí tí ẹ ṣiṣẹ́ kára láti gbìn;+ àti Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé* níparí ọdún, nígbà tí ẹ bá kórè gbogbo ohun tí ẹ gbìn sí oko.+

  • Nọ́ńbà 29:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “‘Ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Ẹ má ṣe iṣẹ́ agbára kankan, kí ẹ sì fi ọjọ́ méje+ ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà.

  • Diutarónómì 16:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 “Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà,+ nígbà tí o bá kó ọkà rẹ jọ láti ibi ìpakà, tí o sì mú òróró àti wáìnì jáde láti ibi ìfúntí rẹ.

  • Ẹ́sírà 3:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lákọsílẹ̀,+ ojoojúmọ́ ni wọ́n sì máa ń rú iye ẹbọ sísun tó yẹ kí wọ́n rú lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.+

  • Nehemáyà 8:14-18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Wọ́n wá rí i nínú Òfin pé Jèhófà pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé inú àtíbàbà ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbé nígbà àjọyọ̀ ní oṣù keje+ 15 àti pé kí wọ́n polongo,+ kí wọ́n sì kéde káàkiri gbogbo ìlú wọn àti ní gbogbo Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ lọ sí àwọn agbègbè olókè, kí ẹ sì mú ẹ̀ka eléwé igi ólífì, ti igi ahóyaya, ti igi mátílì àti imọ̀ ọ̀pẹ pẹ̀lú ẹ̀ka àwọn igi míì tó léwé dáadáa wá láti fi wọ́n ṣe àtíbàbà, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀.”

      16 Ni àwọn èèyàn náà bá jáde lọ, wọ́n sì kó wọn wá láti fi wọ́n ṣe àtíbàbà fún ara wọn, kálukú sórí òrùlé rẹ̀ àti sí àgbàlá wọn àti àgbàlá ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ bákan náà, wọ́n ṣe é sí gbàgede ìlú ní Ẹnubodè Omi+ àti gbàgede ìlú tó wà ní Ẹnubodè Éfúrémù.+ 17 Bí gbogbo àwùjọ* àwọn tó dé láti ìgbèkùn ṣe ṣe àwọn àtíbàbà nìyẹn, wọ́n sì ń gbé inú àwọn àtíbàbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tíì ṣe é báyìí rí láti ìgbà ayé Jóṣúà+ ọmọ Núnì títí di ọjọ́ yẹn, ìdí nìyẹn tí ìdùnnú fi ṣubú layọ̀ láàárín wọn.+ 18 Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń ka ìwé Òfin Ọlọ́run tòótọ́,+ láti ọjọ́ àkọ́kọ́ títí di ọjọ́ tó kẹ́yìn. Wọ́n sì fi ọjọ́ méje ṣe àjọyọ̀ náà, ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n ṣe àpéjọ ọlọ́wọ̀, gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe sọ.+

  • Jòhánù 7:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn*+ tí àwọn Júù máa ń ṣe ti sún mọ́lé.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́