-
Léfítíkù 23:34-36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje yìí ni Àjọyọ̀ Àtíbàbà fún Jèhófà, ọjọ́ méje ni kí ẹ fi ṣe é.+ 35 Àpéjọ mímọ́ yóò wà ní ọjọ́ kìíní, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 36 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Ní ọjọ́ kẹjọ, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́,+ kí ẹ sì ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Àpéjọ ọlọ́wọ̀ ni. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan.
-
-
Diutarónómì 16:13-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 “Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà,+ nígbà tí o bá kó ọkà rẹ jọ láti ibi ìpakà, tí o sì mú òróró àti wáìnì jáde láti ibi ìfúntí rẹ. 14 Máa yọ̀ nígbà àjọyọ̀ rẹ,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ, ẹrúbìnrin rẹ, ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó, tí wọ́n wà nínú àwọn ìlú rẹ. 15 Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe àjọyọ̀+ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ibi tí Jèhófà bá yàn, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún gbogbo ohun tí o bá kórè àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,+ wàá sì máa láyọ̀ nígbà gbogbo.+
-
-
Nehemáyà 8:14-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Wọ́n wá rí i nínú Òfin pé Jèhófà pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé inú àtíbàbà ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbé nígbà àjọyọ̀ ní oṣù keje+ 15 àti pé kí wọ́n polongo,+ kí wọ́n sì kéde káàkiri gbogbo ìlú wọn àti ní gbogbo Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ lọ sí àwọn agbègbè olókè, kí ẹ sì mú ẹ̀ka eléwé igi ólífì, ti igi ahóyaya, ti igi mátílì àti imọ̀ ọ̀pẹ pẹ̀lú ẹ̀ka àwọn igi míì tó léwé dáadáa wá láti fi wọ́n ṣe àtíbàbà, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀.”
16 Ni àwọn èèyàn náà bá jáde lọ, wọ́n sì kó wọn wá láti fi wọ́n ṣe àtíbàbà fún ara wọn, kálukú sórí òrùlé rẹ̀ àti sí àgbàlá wọn àti àgbàlá ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ bákan náà, wọ́n ṣe é sí gbàgede ìlú ní Ẹnubodè Omi+ àti gbàgede ìlú tó wà ní Ẹnubodè Éfúrémù.+ 17 Bí gbogbo àwùjọ* àwọn tó dé láti ìgbèkùn ṣe ṣe àwọn àtíbàbà nìyẹn, wọ́n sì ń gbé inú àwọn àtíbàbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tíì ṣe é báyìí rí láti ìgbà ayé Jóṣúà+ ọmọ Núnì títí di ọjọ́ yẹn, ìdí nìyẹn tí ìdùnnú fi ṣubú layọ̀ láàárín wọn.+ 18 Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń ka ìwé Òfin Ọlọ́run tòótọ́,+ láti ọjọ́ àkọ́kọ́ títí di ọjọ́ tó kẹ́yìn. Wọ́n sì fi ọjọ́ méje ṣe àjọyọ̀ náà, ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n ṣe àpéjọ ọlọ́wọ̀, gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe sọ.+
-