ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 4:29
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 “Tí ẹ bá wá Jèhófà Ọlọ́run yín níbẹ̀, ó dájú pé ẹ máa rí i+ tí ẹ bá fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín wá a.+

  • Diutarónómì 30:1-4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 “Tí gbogbo ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹ sí ọ lára, ìbùkún àti ègún tí mo fi síwájú rẹ,+ tí o sì rántí wọn*+ ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí, 2 tí o wá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, tí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara*+ rẹ fetí sí ohùn rẹ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, 3 nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú+ pa dà wá, ó máa ṣàánú+ rẹ, ó sì máa kó ọ jọ látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí. 4 Ì báà jẹ́ ìpẹ̀kun ọ̀run ni àwọn èèyàn rẹ tú ká sí, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa kó ọ jọ, á sì mú ọ pa dà wá  + láti ibẹ̀.

  • 1 Àwọn Ọba 8:47, 48
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 47 tí wọ́n bá ro inú ara wọn wò ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ,+ tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ,+ tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o ṣojú rere sí àwọn ní ilẹ̀ àwọn tó mú wọn lẹ́rú,+ tí wọ́n sọ pé, ‘A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣàṣìṣe; a ti ṣe ohun búburú,’+ 48 tí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn+ àti gbogbo ara* wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá tó kó wọn lọ sóko ẹrú, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ ní ìdojúkọ ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn àti ìlú tí o yàn àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+

  • Jeremáyà 24:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Màá fún wọn ní ọkàn tí á jẹ́ kí wọ́n fẹ́ láti mọ̀ mí, pé èmi ni Jèhófà.+ Wọ́n á di èèyàn mi, màá sì di Ọlọ́run wọn,+ nítorí wọ́n á fi gbogbo ọkàn wọn pa dà sọ́dọ̀ mi.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́