5 “Pa dà lọ sọ fún Hẹsikáyà aṣáájú àwọn èèyàn mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ sọ nìyí: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ. Mo ti rí omijé rẹ.+ Wò ó, màá mú ọ lára dá.+ Ní ọ̀túnla, wàá lọ sí ilé Jèhófà.+
9 Àìsáyà fèsì pé: “Àmì tí Jèhófà fún ọ nìyí láti mú un dá ọ lọ́jú pé Jèhófà máa mú ọ̀rọ̀ tó sọ ṣẹ: Ṣé o fẹ́ kí òjìji tó wà lórí àtẹ̀gùn* lọ síwájú ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá tàbí kó pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá?”+
31 Àmọ́ nígbà tí wọ́n rán àwọn agbẹnusọ àwọn olórí Bábílónì sí i láti béèrè àmì*+ tó wáyé ní ilẹ̀ náà,+ Ọlọ́run tòótọ́ fi í sílẹ̀ láti dán an wò,+ kó lè mọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.+
8 Màá mú kí òjìji oòrùn tó ń sọ̀ kalẹ̀ lórí àtẹ̀gùn* Áhásì pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.”’”+ Oòrùn wá pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá lẹ́yìn tó ti kọ́kọ́ lọ síwájú lórí àtẹ̀gùn náà.