5 “Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ máa ṣe sí wọn nìyí: Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ sì wó àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn,+ ẹ gé àwọn òpó òrìṣà* wọn,+ kí ẹ sì dáná sun àwọn ère gbígbẹ́ wọn.+
4 Òun ló mú àwọn ibi gíga kúrò,+ tó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́, tó sì gé òpó òrìṣà*+ lulẹ̀. Ó tún fọ́ ejò bàbà tí Mósè ṣe;+ torí pé títí di àkókò yẹn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń mú ẹbọ rú èéfín sí i, tí wọ́n sì ń pè é ní òrìṣà ejò bàbà.*
2 Ásà ṣe ohun tó dára tó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. 3 Ó mú àwọn pẹpẹ àjèjì+ àti àwọn ibi gíga kúrò, ó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́,+ ó sì gé àwọn òpó òrìṣà lulẹ̀.*+
3 Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀, nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀;+ ní ọdún kejìlá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ibi gíga+ àti àwọn òpó òrìṣà* àti àwọn ère gbígbẹ́+ pẹ̀lú àwọn ère onírin* kúrò ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+