ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 32:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ó gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn, ó lo irinṣẹ́ àwọn tó ń fín nǹkan láti fi mọ ọ́n, ó sì fi ṣe ère* ọmọ màlúù.+ Wọ́n wá ń sọ pé: “Ìwọ Ísírẹ́lì, Ọlọ́run rẹ nìyí, òun ló mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+

  • Diutarónómì 7:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 “Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ máa ṣe sí wọn nìyí: Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ sì wó àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn,+ ẹ gé àwọn òpó òrìṣà* wọn,+ kí ẹ sì dáná sun àwọn ère gbígbẹ́ wọn.+

  • Diutarónómì 7:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Kí ẹ dáná sun ère àwọn ọlọ́run wọn tí wọ́n gbẹ́.+ Má ṣe jẹ́ kí ojú rẹ wọ fàdákà àti wúrà tó wà lára wọn, o ò sì gbọ́dọ̀ mú un fún ara rẹ,+ kó má bàa jẹ́ ìdẹkùn fún ọ, torí ohun ìríra ló jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+

  • Àwọn Onídàájọ́ 17:3, 4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ó wá kó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún (1,100) ẹyọ fàdákà náà pa dà fún ìyá rẹ̀, àmọ́ ìyá rẹ̀ sọ pé: “Ó dájú pé màá ya fàdákà náà sí mímọ́ fún Jèhófà látọwọ́ mi, kí ọmọ mi lè fi ṣe ère gbígbẹ́ àti ère onírin.*+ Mo fún ọ pa dà báyìí.”

      4 Lẹ́yìn tó dá fàdákà náà pa dà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ mú igba (200) ẹyọ fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà. Ó ṣe ère gbígbẹ́ àti ère onírin;* wọ́n sì gbé e sínú ilé Míkà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́