ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 2:2, 3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,*

      Òkè ilé Jèhófà

      Máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in sórí àwọn òkè,+

      A sì máa gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,

      Gbogbo orílẹ̀-èdè á sì máa rọ́ lọ síbẹ̀.+

       3 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa lọ, wọ́n á sì sọ pé:

      “Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sórí òkè Jèhófà,

      Sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù.+

      Ó máa kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀,

      A ó sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”+

      Torí òfin* máa jáde láti Síónì,

      Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì máa jáde láti Jerúsálẹ́mù.+

  • Àìsáyà 56:6, 7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Ní ti àwọn àjèjì tó fara mọ́ Jèhófà láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un,

      Láti nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà,+

      Kí wọ́n sì di ìránṣẹ́ rẹ̀,

      Gbogbo àwọn tó ń pa Sábáàtì mọ́, tí wọn ò sì kẹ́gàn rẹ̀,

      Tí wọ́n ń rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi,

       7 Màá tún mú wọn wá sí òkè mímọ́ mi,+

      Màá sì mú kí wọ́n máa yọ̀ nínú ilé àdúrà mi.

      Màá tẹ́wọ́ gba odindi ẹbọ sísun wọn àtàwọn ẹbọ wọn lórí pẹpẹ mi.

      Torí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo èèyàn.”+

  • Àìsáyà 60:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 Àwọn orílẹ̀-èdè máa lọ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ,+

      Àwọn ọba+ sì máa lọ sínú ẹwà rẹ tó ń tàn.*+

  • Míkà 4:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,*

      Òkè ilé Jèhófà+

      Máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in sórí àwọn òkè,

      A sì máa gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,

      Àwọn èèyàn á sì máa rọ́ lọ síbẹ̀.+

       2 Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa lọ, wọ́n á sì sọ pé:

      “Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sórí òkè Jèhófà,

      Sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù.+

      Ó máa kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀,

      A ó sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”

      Torí òfin* máa jáde láti Síónì,

      Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì máa jáde láti Jerúsálẹ́mù.

  • Sekaráyà 2:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 “Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò fara mọ́ Jèhófà ní ọjọ́ náà,+ wọ́n á sì di èèyàn mi; èmi yóò sì máa gbé láàárín yín.” Ẹ ó sì mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló rán mi sí yín.

  • Sekaráyà 8:22, 23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Ọ̀pọ̀ èèyàn àti orílẹ̀-èdè alágbára yóò wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ kí wọ́n sì lè bẹ Jèhófà pé kó ṣojúure sí àwọn.’*

      23 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ní àwọn ọjọ́ yẹn, ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè+ yóò di aṣọ* Júù* kan mú, àní wọn yóò dì í mú ṣinṣin, wọ́n á sì sọ pé: “A fẹ́ bá yín lọ,+ torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́