-
Jeremáyà 32:28, 29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó, màá fi ìlú yìí lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà àti Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, á sì gbà á.+ 29 Àwọn ará Kálídíà tó ń bá ìlú yìí jà máa wọlé wá, wọ́n á sọ iná sí i, wọ́n á sì sun ún kanlẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ilé tí àwọn èèyàn náà ti ń rú ẹbọ lórí òrùlé wọn sí Báálì, tí wọ́n sì ti ń da ọrẹ ohun mímu sí àwọn ọlọ́run míì láti mú mi bínú.’+
-