-
Jeremáyà 31:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Màá mú wọn pa dà wá láti ilẹ̀ àríwá.+
Màá sì kó wọn jọ láti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+
Àwọn afọ́jú àti àwọn arọ máa wà lára wọn,+
Aboyún àti ẹni tó ń rọbí, gbogbo wọn pa pọ̀.
Bí ìjọ ńlá ni wọ́n máa pa dà sí ibí yìí.+
9 Wọ́n á wá pẹ̀lú ẹkún.+
Màá máa darí wọn bí wọ́n ṣe ń wá ojú rere.
Nítorí èmi ni Bàbá Ísírẹ́lì, Éfúrémù sì ni àkọ́bí mi.”+
-