ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 13:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Màá gbé wọn kọ lu ara wọn, àwọn bàbá àti àwọn ọmọ,” ni Jèhófà wí.+ “Mi ò ní yọ́nú sí wọn tàbí kí n bá wọn kẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò ní ṣàánú wọn. Kò sì sí ohun tó máa dá mi dúró láti pa wọ́n run.”’+

  • Jeremáyà 21:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 “‘Jèhófà sọ pé, “Lẹ́yìn náà, màá fi Sedekáyà ọba Júdà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn ìlú yìí, ìyẹn àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn, idà àti ìyàn, lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn.*+ Á fi idà pa wọ́n. Kò ní bá wọn kẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní yọ́nú sí wọn tàbí kó ṣàánú wọn.”’+

  • Ìdárò 3:43
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 43 O ti fi ìbínú dí ọ̀nà àdúrà wa;+

      O lé wa, o sì pa wá láìṣàánú.+

  • Ìsíkíẹ́lì 5:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 “‘Torí náà, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘torí pé ẹ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín àti àwọn ohun ìríra tí ẹ̀ ń ṣe sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ èmi náà yóò kọ̀ yín;* mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín.+

  • Ìsíkíẹ́lì 9:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Ẹ pa àwọn àgbàlagbà ọkùnrin pátápátá àti àwọn géńdé ọkùnrin, wúńdíá, ọmọdé àti àwọn obìnrin.+ Àmọ́ ẹ má ṣe sún mọ́ ẹnikẹ́ni tí àmì náà wà lórí rẹ̀.+ Ibi mímọ́ mi ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀.”+ Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà níwájú ilé náà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́