-
Léfítíkù 5:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Kó tún mú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ wá fún Jèhófà torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá,+ ìyẹn abo ẹran látinú agbo ẹran láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ó lè jẹ́ abo ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí abo ọmọ ewúrẹ́. Àlùfáà yóò wá ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
-
-
Léfítíkù 7:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 “‘Òfin ẹbọ ẹ̀bi+ nìyí: Ohun mímọ́ jù lọ ni.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 42:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ó wá sọ fún mi pé: “Yàrá ìjẹun mímọ́ ni àwọn yàrá ìjẹun tó wà ní àríwá àti àwọn èyí tó wà ní gúúsù tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àyè fífẹ̀ yẹn,+ ibẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí wọ́n ń wá síwájú Jèhófà ti máa ń jẹ àwọn ọrẹ mímọ́ jù lọ.+ Ibẹ̀ ni wọ́n ń gbé àwọn ọrẹ mímọ́ jù lọ sí àti ọrẹ ọkà, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi, torí pé ibi mímọ́ ni.+
-