ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 6:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 “‘Òfin ọrẹ ọkà+ nìyí: Kí ẹ̀yin ọmọ Áárónì mú un wá síwájú Jèhófà, ní iwájú pẹpẹ.

  • Léfítíkù 6:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ ohun tó bá ṣẹ́ kù lára rẹ̀.+ Kí wọ́n fi ṣe búrẹ́dì aláìwú, kí wọ́n jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́. Kí wọ́n jẹ ẹ́ ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé.+

  • Léfítíkù 7:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 “‘Òfin ẹbọ ẹ̀bi+ nìyí: Ohun mímọ́ jù lọ ni.

  • Léfítíkù 7:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Kí gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ àlùfáà jẹ ẹ́,+ ibi mímọ́ ni kí wọ́n sì ti jẹ ẹ́. Ohun mímọ́ jù lọ ni.+

  • Léfítíkù 10:12, 13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Mósè wá sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Élíásárì àti Ítámárì pé: “Ẹ kó ọrẹ ọkà tó ṣẹ́ kù látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, kí ẹ fi ṣe búrẹ́dì aláìwú, kí ẹ sì jẹ ẹ́ nítòsí pẹpẹ,+ torí pé ohun mímọ́ jù lọ ni.+ 13 Kí ẹ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́,+ torí ìpín tìrẹ àti ìpín àwọn ọmọ rẹ látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ni, torí pé àṣẹ tí mo gbà nìyí.

  • Léfítíkù 24:8, 9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Kó máa tò ó síwájú Jèhófà nígbà gbogbo+ ní ọjọ́ Sábáàtì kọ̀ọ̀kan. Májẹ̀mú tí mo bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá ni, ó sì máa wà títí lọ. 9 Yóò di ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ wọ́n á sì jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́,+ torí ó jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ fún un látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, ìlànà tó máa wà títí lọ ni.”

  • Nọ́ńbà 18:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Inú ibi mímọ́ jù lọ ni kí o ti jẹ ẹ́.+ Gbogbo ọkùnrin ló lè jẹ ẹ́. Kó jẹ́ ohun mímọ́ fún ọ.+

  • Ìsíkíẹ́lì 40:46
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 46 Yàrá ìjẹun tó dojú kọ àríwá wà fún àwọn àlùfáà tó ń bójú tó iṣẹ́ pẹpẹ.+ Àwọn ni ọmọ Sádókù,+ àwọn ni àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n yàn láti máa wá síwájú Jèhófà kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ fún un.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́