ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 2:7, 8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Jèhófà ń sọni di aláìní, ó sì ń sọni di ọlọ́rọ̀;+

      Ó ń rẹni wálẹ̀, ó sì ń gbéni ga.+

       8 Ó ń gbé aláìní dìde látinú eruku;

      Ó ń gbé tálákà dìde látinú eérú,*+

      Láti mú kí wọ́n jókòó pẹ̀lú àwọn olórí,

      Ó fún wọn ní ìjókòó iyì.

      Ti Jèhófà ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé,+

      Ó sì gbé ilẹ̀ tó ń mú èso jáde ka orí wọn.

  • Jóòbù 34:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Ó ń fọ́ àwọn alágbára túútúú láì ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣèwádìí,

      Ó sì ń fi àwọn míì rọ́pò wọn.+

  • Jeremáyà 27:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 ‘Èmi ni mo dá ayé, èèyàn àti ẹranko tó wà lórí ilẹ̀ nípa agbára ńlá mi àti nípa apá mi tí mo nà jáde, mo sì ti fún ẹni tí mo fẹ́.*+

  • Ìsíkíẹ́lì 21:26, 27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Tú láwàní, kí o sì ṣí adé.+ Èyí ò ní rí bíi ti tẹ́lẹ̀.+ Gbé ẹni tó rẹlẹ̀ ga,+ kí o sì rẹ ẹni gíga wálẹ̀.+ 27 Àwókù, àwókù, ṣe ni màá sọ ọ́ di àwókù. Kò ní jẹ́ ti ẹnì kankan títí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin fi máa dé,+ òun sì ni èmi yóò fún.’+

  • Dáníẹ́lì 2:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Ó ń yí ìgbà àti àsìkò pa dà,+

      Ó ń mú ọba kúrò, ó sì ń fi ọba jẹ,+

      Ó ń fún àwọn ọlọ́gbọ́n ní ọgbọ́n, ó sì ń fún àwọn tó ní òye ní ìmọ̀.+

  • Dáníẹ́lì 7:13, 14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 “Mò ń wò nínú ìran òru, sì wò ó! ẹnì kan bí ọmọ èèyàn+ ń bọ̀ pẹ̀lú ìkùukùu* ojú ọ̀run; a jẹ́ kó wọlé wá sọ́dọ̀ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,+ wọ́n sì mú un wá sún mọ́ iwájú Ẹni yẹn. 14 A sì fún un ní àkóso,+ ọlá+ àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà máa sìn ín.+ Àkóso rẹ̀ jẹ́ àkóso tó máa wà títí láé, tí kò ní kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ ò sì ní pa run.+

  • Lúùkù 1:32, 33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá,+ wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ,+ Jèhófà* Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀,+ 33 ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́