ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 12:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Jèhófà sì sọ fún Ábúrámù pé: “Kúrò ní ilẹ̀ rẹ, kí o kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ àti ilé bàbá rẹ, kí o lọ sí ilẹ̀ tí màá fi hàn ọ́.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 12:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Màá súre fún àwọn tó ń súre fún ọ, màá sì gégùn-ún fún ẹni tó bá gégùn-ún fún ọ,+ ó dájú pé gbogbo ìdílé tó wà lórí ilẹ̀ yóò rí ìbùkún gbà* nípasẹ̀ rẹ.”+

  • Jẹ́nẹ́sísì 28:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Torí náà, Ísákì pe Jékọ́bù, ó súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé: “O ò gbọ́dọ̀ fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ọmọ Kénáánì!+

  • Jẹ́nẹ́sísì 28:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ọlọ́run Olódùmarè yóò bù kún ọ, yóò mú kí o bímọ tó pọ̀, yóò mú kí o pọ̀ gan-an, ó sì dájú pé ìwọ yóò di àwùjọ àwọn èèyàn.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 31:42
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 42 Ká ní Ọlọ́run bàbá mi,+ Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ẹni tí Ísákì ń bẹ̀rù*+ kò tì mí lẹ́yìn ni, ọwọ́ òfo lò bá ní kí n kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ọlọ́run ti rí ìyà tó ń jẹ mí àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ́ mi ṣe, ìdí nìyẹn tó fi bá ọ wí lóru àná.”+

  • Ìsíkíẹ́lì 25:12, 13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Édómù ti gbẹ̀san lára ilé Júdà, wọ́n sì ti jẹ̀bi gidigidi torí ẹ̀san tí wọ́n gbà;+ 13 torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá tún na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ Édómù, èmi yóò pa àwọn èèyàn àti ẹran ọ̀sìn ibẹ̀, èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro.+ Idà ni yóò pa wọ́n láti Témánì títí dé Dédánì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́