ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 4:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Tí o bá dé Íjíbítì, rí i pé gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí mo fún ọ lágbára láti ṣe lo ṣe níwájú Fáráò.+ Àmọ́, màá jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ le,+ kò sì ní jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lọ.+

  • Ẹ́kísódù 7:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Síbẹ̀, ọkàn Fáráò le,+ kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.

  • Ẹ́kísódù 7:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Síbẹ̀, àwọn àlùfáà onídán ní Íjíbítì fi agbára òkùnkùn wọn ṣe ohun kan náà,+ ìyẹn sì mú kí ọkàn Fáráò túbọ̀ le, kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.+

  • Ẹ́kísódù 8:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Nígbà tí Fáráò rí i pé ìtura dé, ó tún mú ọkàn rẹ̀ le,+ kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.

  • Ẹ́kísódù 8:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Torí náà, àwọn àlùfáà onídán sọ fún Fáráò pé: “Ìka Ọlọ́run nìyí!”+ Àmọ́ ọkàn Fáráò ṣì le, kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.

  • Ẹ́kísódù 9:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Àmọ́ Jèhófà jẹ́ kí ọkàn Fáráò le, kò sì fetí sí wọn, bí Jèhófà ṣe sọ fún Mósè.+

  • Ẹ́kísódù 9:35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 35 Fáráò ò yí ọkàn rẹ̀ pa dà, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ, bí Jèhófà ṣe gbẹnu Mósè sọ.+

  • Ẹ́kísódù 10:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Síbẹ̀, Jèhófà jẹ́ kí ọkàn Fáráò le,+ kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

  • Ẹ́kísódù 10:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Jèhófà jẹ́ kí ọkàn Fáráò le, kò sì gbà kí wọ́n lọ.+

  • Ẹ́kísódù 11:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Mósè àti Áárónì ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu yìí níwájú Fáráò,+ àmọ́ Jèhófà jẹ́ kí ọkàn Fáráò le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.+

  • Ẹ́kísódù 14:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí ọkàn Fáráò ọba Íjíbítì le nìyẹn, ó sì ń lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì balẹ̀* bí wọ́n ṣe ń lọ.+

  • Róòmù 9:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ fún Fáráò pé: “Ìdí tí mo fi jẹ́ kí o máa wà nìṣó ni pé: kí n lè fi agbára mi hàn nípasẹ̀ rẹ àti pé kí a lè ròyìn orúkọ mi ní gbogbo ayé.”+ 18 Torí náà, ẹni tó bá wù ú ló ń ṣàánú, ẹni tó bá sì wù ú ló ń jẹ́ kó di olóríkunkun.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́