-
Ẹ́kísódù 15:14-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ gbọ́,+ jìnnìjìnnì á bò wọ́n;
Àwọn tó ń gbé Filísíà máa jẹ̀rora.*
15 Ní àkókò yẹn, ẹ̀rù yóò ba àwọn séríkí* Édómù,
Àwọn alágbára tó ń ṣàkóso Móábù* yóò gbọ̀n rìrì.+
Ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé ní Kénáánì yóò domi.+
16 Ìbẹ̀rù àti jìnnìjìnnì yóò bò wọ́n.+
Ọwọ́ ńlá rẹ yóò mú kí wọ́n dúró sójú kan bí òkúta
Títí àwọn èèyàn rẹ yóò fi kọjá, Jèhófà,
-
-
Jóṣúà 2:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ó sì sọ fún wọn pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà máa fún yín ní ilẹ̀ yìí+ àti pé ẹ̀rù yín ti ń bà wá.+ Ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí sì ti domi nítorí yín,+ 10 torí a ti gbọ́ bí Jèhófà ṣe mú kí omi Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì+ àti ohun tí ẹ ṣe sí àwọn ọba Ámórì méjèèjì, ìyẹn Síhónì+ àti Ógù+ tí ẹ pa run ní òdìkejì* Jọ́dánì. 11 Nígbà tí a gbọ́ nípa rẹ̀, ọkàn wa domi,* kò sì sẹ́ni tó ní ìgboyà* mọ́ nítorí yín, torí Jèhófà Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.+
-