ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 49:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ọ̀pá àṣẹ kò ní kúrò lọ́dọ̀ Júdà,+ ọ̀pá aláṣẹ kò sì ní kúrò láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ títí Ṣílò* yóò fi dé,+ òun ni àwọn èèyàn yóò máa ṣègbọràn sí.+

  • 1 Sámúẹ́lì 16:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Níkẹyìn, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Ìgbà wo lo máa ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù dà,+ ní báyìí tí mo ti kọ Sọ́ọ̀lù pé kí ó má ṣe jẹ́ ọba lórí Ísírẹ́lì mọ́?+ Rọ òróró sínú ìwo,+ kí o sì lọ. Màá rán ọ lọ sọ́dọ̀ Jésè+ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nítorí mo ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ ọba fún mi.”+

  • 1 Sámúẹ́lì 25:30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Tí Jèhófà bá ti ṣe gbogbo ohun rere tí ó ṣèlérí fún olúwa mi, tí ó sì fi ọ́ ṣe olórí Ísírẹ́lì,+

  • 2 Sámúẹ́lì 6:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Ni Dáfídì bá sọ fún Míkálì pé: “Iwájú Jèhófà ni mo ti ń ṣe àjọyọ̀, òun ni ó yàn mí dípò bàbá rẹ àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ láti fi mí ṣe aṣáájú Ísírẹ́lì+ tó jẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà. Torí náà, màá ṣe àjọyọ̀ níwájú Jèhófà,

  • 2 Sámúẹ́lì 7:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ní báyìí, sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo mú ọ láti ibi ìjẹko, pé kí o má da agbo ẹran mọ́,+ kí o lè wá di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+

  • 1 Kíróníkà 28:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Síbẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì yàn mí nínú gbogbo ilé bàbá mi láti di ọba lórí Ísírẹ́lì títí láé,+ nítorí ó yan Júdà ṣe aṣáájú,+ nínú gbogbo ilé Júdà, ó yan ilé bàbá mi,+ nínú gbogbo ọmọ bàbá mi, èmi ni ó fọwọ́ sí, láti fi mí jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+

  • Sáàmù 78:71
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 71 Kúrò ní ibi tó ti ń tọ́jú àwọn abo àgùntàn tó ń fọ́mọ lọ́mú;

      Ó fi í ṣe olùṣọ́ àgùntàn lórí Jékọ́bù, àwọn èèyàn rẹ̀+

      Àti lórí Ísírẹ́lì, ogún rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́