-
Léfítíkù 18:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 “‘Ẹ má fi èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan yìí sọ ara yín di aláìmọ́, torí gbogbo àwọn nǹkan yìí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fẹ́ lé kúrò níwájú yín fi sọ ara wọn di aláìmọ́.+
-
-
2 Kíróníkà 33:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Mánásè ń ṣi Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù lọ́nà nìṣó, ó ń mú kí wọ́n ṣe ohun tó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa run kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
-
-
Jeremáyà 3:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Àwọn èèyàn béèrè pé: “Bí ọkùnrin kan bá lé ìyàwó rẹ̀ lọ, tí obìnrin náà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, tó sì lọ fẹ́ ọkùnrin míì, ṣé ó yẹ kí ọkùnrin náà tún lọ bá obìnrin yẹn?”
Ǹjẹ́ wọn ò ti sọ ilẹ̀ náà di ẹlẹ́gbin pátápátá?+
“O ti bá ọ̀pọ̀ àwọn tí ò ń bá kẹ́gbẹ́ ṣe ìṣekúṣe,+
Ṣé ó wá yẹ kí o pa dà sọ́dọ̀ mi?” ni Jèhófà wí.
-