ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Sefanáyà 1:1-3:20
  • Sefanáyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sefanáyà
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sefanáyà

SEFANÁYÀ

1 Ọ̀rọ̀ Jèhófà sí Sefanáyà* ọmọ Kúúṣì, ọmọ Gẹdaláyà, ọmọ Amaráyà, ọmọ Hẹsikáyà nígbà ayé Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì+ ọba Júdà:

 2 “Màá pa ohun gbogbo rẹ́ ráúráú kúrò lórí ilẹ̀,” ni Jèhófà wí.+

 3 “Màá pa èèyàn àti ẹranko rẹ́.

Màá pa ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹja inú òkun rẹ́+

Àti àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀*+ pẹ̀lú àwọn èèyàn burúkú;

Màá sì mú àwọn èèyàn kúrò lórí ilẹ̀,” ni Jèhófà wí.

 4 “Màá na ọwọ́ mi sórí Júdà

Àti sórí gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù,

Gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó ń sin* Báálì+ ní ibí yìí ni màá sì pa rẹ́,

Àti orúkọ àwọn àlùfáà ọlọ́run àjèjì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àlùfáà míì,+

 5 Àti àwọn tó ń forí balẹ̀ lórí òrùlé fún àwọn ọmọ ogun ọ̀run+

Àti àwọn tó ń forí balẹ̀, tí wọ́n ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ti Jèhófà+ làwọn ń ṣe

Lẹ́sẹ̀ kan náà, tí wọ́n ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ti Málíkámù làwọn ń ṣe;+

 6 Àti àwọn tó pa dà lẹ́yìn Jèhófà+

Àti àwọn tí kò wá Jèhófà tàbí àwọn tí kò wádìí nípa rẹ̀.”+

 7 Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé.+

Jèhófà ti pèsè ẹbọ sílẹ̀, ó sì ti ya àwọn tí ó pè sí mímọ́.

 8 “Ní ọjọ́ tí Jèhófà pèsè ẹbọ, màá pe àwọn ìjòyè wá jíhìn,

Àwọn ọmọ ọba+ àti gbogbo àwọn tó ń wọ aṣọ ilẹ̀ òkèèrè.

 9 Màá sì pe gbogbo ẹni tó ń gun pèpéle* wá jíhìn ní ọjọ́ yẹn,

Àwọn tó ń mú kí ìwà ipá àti ẹ̀tàn gbilẹ̀ ní ilé ọ̀gá wọn.

10 Ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà wí,

“Igbe ẹkún máa wá láti Ẹnubodè Ẹja+

Àti ìpohùnréré ẹkún láti Apá Kejì ìlú náà+

Àti ìfọ́yángá láti àwọn òkè.

11 Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin tó ń gbé Mákítẹ́ṣì,*

Torí pé gbogbo àwọn oníṣòwò* ni wọ́n ti pa rẹ́;*

Gbogbo àwọn tó ń wọn fàdákà ni wọ́n sì ti pa run.

12 Ní àkókò yẹn, màá fi fìtílà wá inú Jerúsálẹ́mù fínnífínní,

Màá sì pe àwọn tó dẹra nù* wá jíhìn, àwọn tó ń sọ nínú ọkàn wọn pé,

‘Jèhófà kò ní ṣe rere, kò sì ní ṣe búburú.’+

13 Wọ́n á kó ọrọ̀ wọn lọ, wọ́n á sì pa ilé wọn run.+

Wọ́n á kọ́ ilé, ṣùgbọ́n wọn kò ní gbé inú rẹ̀;

Wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kò ní mu wáìnì rẹ̀.+

14 Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé!+

Ó sún mọ́lé, ó sì ń yára bọ̀ kánkán!*+

Ìró ọjọ́ Jèhófà korò.+

Akíkanjú ológun máa figbe ta níbẹ̀.+

15 Ọjọ́ yẹn jẹ́ ọjọ́ ìbínú ńlá,+

Ọjọ́ wàhálà àti ìdààmú,+

Ọjọ́ ìjì àti ìsọdahoro,

Ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,+

Ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà,+

16 Ọjọ́ ìwo àti ariwo ogun,+

Lòdì sí àwọn ìlú olódi àti sí àwọn ilé gogoro tó wà ní àwọn ìkángun odi.+

17 Màá fa wàhálà bá aráyé,

Wọ́n á sì máa rìn bí afọ́jú,+

Nítorí pé wọ́n ti ṣẹ Jèhófà.+

A ó tú ẹ̀jẹ̀ wọn jáde bí eruku

Àti ẹran ara* wọn bí ìgbẹ́.+

18 Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú ńlá Jèhófà;+

Torí ìtara rẹ̀ tó ń jó bí iná máa jó gbogbo ayé run,+

Nítorí ó máa pa àwọn èèyàn ayé nípakúpa, àní á pa wọ́n yán-án yán-án.”+

2 Ẹ kóra jọ, bẹ́ẹ̀ ni, ẹ kó ara yín jọ,+

Ẹ̀yin èèyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú.+

 2 Kí àṣẹ náà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́,

Kí ọjọ́ náà tó kọjá lọ bí ìyàngbò,*

Kí ìbínú tó ń jó fòfò látọ̀dọ̀ Jèhófà tó wá sórí yín,+

Kí ọjọ́ ìbínú Jèhófà tó dé bá yín,

 3 Ẹ wá Jèhófà,+ gbogbo ẹ̀yin oníwà pẹ̀lẹ́* ayé,

Tó ń pa àṣẹ òdodo* rẹ̀ mọ́.

Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìwà pẹ̀lẹ́.*

Bóyá* ẹ ó rí ààbò ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.+

 4 Nítorí Gásà máa di ìlú tí a pa tì;

Áṣíkẹ́lónì á sì di ahoro.+

Áṣídódì ni wọ́n á lé jáde ní ọ̀sán gangan,*

Ẹ́kírónì ni a ó sì fà tu.+

 5 “Ẹ gbé! Ẹ̀yin tó ń gbé etí òkun, orílẹ̀-èdè àwọn Kérétì.+

Jèhófà ti bá yín wí.

Ìwọ Kénáánì, ilẹ̀ àwọn Filísínì, màá pa ọ́ run,

Tí kò fi ní sí olùgbé kan tó máa ṣẹ́ kù.

 6 Etí òkun náà á di ilẹ̀ ìjẹko,

Tó ní àwọn kànga fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti àwọn ọgbà tí a fi òkúta ṣe fún àwọn àgùntàn.

 7 Á sì di agbègbè fún àwọn tó ṣẹ́ kù lára ilé Júdà;+

Ibẹ̀ ni wọ́n á ti máa jẹun.

Wọ́n á dùbúlẹ̀ sí àwọn ilé Áṣíkẹ́lónì ní ìrọ̀lẹ́.

Nítorí Jèhófà Ọlọ́run wọn máa ṣíjú àánú wò wọ́n,*

Á sì kó àwọn tó wà ní oko ẹrú lára wọn pa dà.”+

 8 “Mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ẹnu Móábù+ àti èébú àwọn ọmọ Ámónì,+

Àwọn tó kẹ́gàn àwọn èèyàn mi, tí wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ wọn láti gba ilẹ̀ wọn.+

 9 Nítorí náà, bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí,

“Móábù máa dà bíi Sódómù gẹ́lẹ́,+

Àti àwọn ọmọ Ámónì bíi Gòmórà,+

Ibi tí èsìsì wà, tí kòtò iyọ̀ wà, tó sì ti di ahoro títí láé.+

Àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn mi á kó wọn lọ,

Àwọn tó ṣẹ́ kù nínú orílẹ̀-èdè mi á sì gba tọwọ́ wọn.

10 Èyí ni ohun tí wọ́n máa gbà nítorí ìgbéraga wọn,+

Torí pé wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì ń gbé ara wọn ga sí àwọn èèyàn Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.

11 Jèhófà máa dẹ́rù bà wọ́n;*

Nítorí ó máa mú kí gbogbo àwọn ọlọ́run tó wà ní ayé di asán,*

Gbogbo erékùṣù àwọn orílẹ̀-èdè á sì forí balẹ̀ fún un,*+

Láti ibi tí kálukú wọn wà.

12 Ẹ̀yin ará Etiópíà, idà mi ni yóò pa ẹ̀yin náà.+

13 Ó máa na ọwọ́ rẹ̀ sí àríwá, á sì pa Ásíríà run,

Á sọ Nínéfè di ahoro,+ á sì gbẹ bí aṣálẹ̀.

14 Àwọn agbo ẹran máa dùbúlẹ̀ sí àárín rẹ̀, gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́.*

Ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀ máa sùn mọ́jú láàárín àwọn ọpọ́n orí òpó rẹ̀.

Ohùn kan á kọrin lójú fèrèsé.*

Ibi àbáwọlé á di ahoro;

Torí pé, ó máa mú kí ilẹ̀kùn kédárì jẹ.

15 Èyí ni ìlú agbéraga tó wà ní ààbò,

Tó ń sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmíì.’

Ẹ wo bó ṣe di ohun àríbẹ̀rù,

Ibi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ dùbúlẹ̀ sí!

Gbogbo ẹni tó bá ń gba ọ̀dọ̀ rẹ̀ kọjá á súfèé, á sì mi orí rẹ̀.”+

3 Ìlú tó ń ṣọ̀tẹ̀ gbé! Ó ti di ẹlẹ́gbin, ó sì ń ni àwọn èèyàn rẹ̀ lára.+

 2 Kò ṣègbọràn;+ kò gba ìbáwí.+

Kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà;+ kò sì sún mọ́ Ọlọ́run rẹ̀.+

 3 Àwọn olórí tó wà nínú rẹ̀ jẹ́ kìnnìún tó ń ké ramúramù.+

Àwọn onídàájọ́ rẹ̀ jẹ́ ìkookò ní alẹ́;

Wọn kì í jẹ egungun kankan kù di òwúrọ̀.

 4 Aláfojúdi ni àwọn wòlíì rẹ̀, oníbékebèke ni wọ́n.+

Àwọn àlùfáà rẹ̀ ń sọ ohun mímọ́ di ẹlẹ́gbin;+

Wọ́n ń rú òfin.+

 5 Jèhófà jẹ́ olódodo ní àárín rẹ̀;+ kò ní ṣe àìtọ́.

Àràárọ̀ ló ń jẹ́ ká mọ ìdájọ́ rẹ̀,+

Kì í yẹ̀ bí ojúmọ́ kì í ti í yẹ̀.

Ṣùgbọ́n àwọn aláìṣòdodo kò ní ìtìjú.+

 6 “Mo pa àwọn orílẹ̀-èdè run; àwọn ilé gogoro tó wà ní àwọn ìkángun odi wọn ti di ahoro.

Mo pa àwọn ojú ọ̀nà wọn run, tí kò fi sí ẹni tó ń gbà á kọjá.

Àwọn ìlú wọn ti di àwókù tí kò sí ẹnì kankan níbẹ̀, tí kò sì ní olùgbé kankan.+

 7 Mo sọ pé, ‘Dájúdájú, wàá bẹ̀rù mi, wàá sì gba ìbáwí,’*+

Kí ibùgbé rẹ̀ má bàa pa run+

Màá pè é wá jíhìn* nítorí gbogbo nǹkan yìí.

Síbẹ̀, ara túbọ̀ ń yá wọn láti hùwàkiwà.+

 8 ‘Nítorí náà, ẹ máa retí mi,’*+ ni Jèhófà wí,

‘Títí di ọjọ́ tí màá wá gba* ohun tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn,

Nítorí ìdájọ́ mi ni láti kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ, kí n sì kó àwọn ìjọba jọ,

Kí n lè da ìrunú mi sórí wọn, gbogbo ìbínú mi tó ń jó fòfò;+

Torí ìtara mi tó ń jó bí iná máa jó gbogbo ayé run.+

 9 Nígbà náà, màá yí èdè àwọn èèyàn pa dà sí èdè mímọ́,

Kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà,

Kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìṣọ̀kan.’*+

10 Láti agbègbè àwọn odò tó wà ní Etiópíà,

Ni àwọn tó ń pàrọwà sí mi, ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi tí wọ́n tú ká, ti máa mú ẹ̀bùn wá fún mi.+

11 Ní ọjọ́ yẹn, ojú ò ní tì ọ́

Nítorí gbogbo ohun tí o ṣe láti fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi,+

Torí nígbà náà, màá mú àwọn agbéraga tó ń fọ́nnu kúrò láàárín rẹ;

O ò sì ní gbéra ga mọ́ ní òkè mímọ́ mi.+

12 Màá jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ àti àwọn aláìní wà ní àárín rẹ,+

Wọ́n á sì fi orúkọ Jèhófà ṣe ibi ààbò.

13 Àwọn tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì+ kò ní hùwà àìṣòdodo;+

Wọn kò ní parọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní fi ahọ́n wọn tanni jẹ;

Wọ́n á jẹun,* wọ́n á sì dùbúlẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”+

14 Kígbe ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì!

Kígbe ìṣẹ́gun, ìwọ Ísírẹ́lì!+

Máa yọ̀, sì jẹ́ kí ayọ̀ kún inú ọkàn rẹ, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù!+

15 Jèhófà ti mú àwọn ìdájọ́ kúrò lórí rẹ.+

Ó ti lé ọ̀tá rẹ dà nù.+

Ọba Ísírẹ́lì, Jèhófà, wà ní àárín rẹ.+

Ìwọ kò ní bẹ̀rù àjálù mọ́.+

16 Ní ọjọ́ yẹn, a ó sọ fún Jerúsálẹ́mù pé:

“Má bẹ̀rù, ìwọ Síónì.+

Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ domi.*

17 Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà ní àárín rẹ.+

Ó máa gbani là bí Alágbára ńlá.

Ó máa yọ̀ gidigidi nítorí rẹ.+

Á dákẹ́ jẹ́ẹ́* nínú ìfẹ́ rẹ̀.

Á dunnú nítorí rẹ pẹ̀lú igbe ayọ̀.

18 Àwọn tí ẹ̀dùn ọkàn bá torí pé wọn ò wá sí àwọn àjọyọ̀ rẹ ni màá kó jọ;+

Wọn ò sí lọ́dọ̀ rẹ torí pé wọ́n wà ní ìgbèkùn, níbi tí wọ́n ti ń kẹ́gàn wọn.+

19 Wò ó! Ní àkókò yẹn, màá dojú ìjà kọ gbogbo àwọn tó ń pọ́n ọ lójú;+

Màá gba ẹni tó ń tiro là,+

Màá sì kó àwọn tó ti fọ́n ká jọ.+

Màá sọ wọ́n di ẹni iyì àti olókìkí*

Ní gbogbo ilẹ̀ tí ìtìjú ti bá wọn.

20 Ní àkókò yẹn, màá mú yín wọlé,

Ní àkókò tí mo kó yín jọ.

Nítorí màá sọ yín di olókìkí* àti ẹni iyì+ láàárín gbogbo aráyé,

Tí mo bá kó àwọn èèyàn yín tó wà ní oko ẹrú pa dà lójú yín,” ni Jèhófà wí.+

Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Pa Á Mọ́ (Fi Ṣúra).”

Ó ṣe kedere pé, àwọn nǹkan tàbí iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà ni.

Tàbí “ìràlẹ̀rálẹ̀.”

Tàbí “etí pèpéle.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pèpéle tí wọ́n ṣe sí ìtẹ́ ọba.

Ó jọ pé apá kan Jerúsálẹ́mù nítòsí Ẹnubodè Ẹja ni.

Tàbí “àwọn olówò.”

Ní Héb., “pa lẹ́nu mọ́.”

Ní Héb., “tó ń dì sórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn,” bó ṣe máa ń rí nínú àgbá wáìnì.

Tàbí “sáré tete.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Ní Héb., “ìfun.”

Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.

Tàbí “ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀.”

Ní Héb., “ìdájọ́ rẹ̀.”

Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀.”

Tàbí “Ó lè jẹ́ pé.”

Tàbí “ọ̀sán ganrínganrín.”

Tàbí “tọ́jú wọn.”

Tàbí “mú kí àyà wọn já.”

Tàbí “rù hangogo.”

Tàbí “jọ́sìn rẹ̀.”

Ní Héb., “ẹranko orílẹ̀-èdè.”

Tàbí “wíńdò.”

Tàbí “ìtọ́sọ́nà.”

Tàbí “jìyà.”

Tàbí “fi sùúrù dúró dè mí.”

Tàbí kó jẹ́, “ṣe ẹlẹ́rìí sí.”

Ní Héb., “ní èjìká kan.”

Tàbí “jẹko.”

Ní Héb., “kí ọwọ́ rẹ wálẹ̀.”

Tàbí “fọkàn balẹ̀; ní ìtẹ́lọ́rùn.”

Ní Héb., “orúkọ kan.”

Ní Héb., “orúkọ kan.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́