NÁHÚMÙ
1 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Nínéfè:+ Èyí ni ìwé tó sọ nípa ìran tí Náhúmù* ará Élíkóṣì rí:
2 Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo,+ ó sì ń gbẹ̀san;
Jèhófà ń gbẹ̀san, ó sì ṣe tán láti bínú.+
Jèhófà ń gbẹ̀san lára àwọn elénìní rẹ̀,
Ó sì ń to ìbínú rẹ̀ jọ de àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú ẹ̀fúùfù àti ìjì líle,
Àwọsánmà sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.+
Báṣánì àti Kámẹ́lì rọ,+
Ìtànná Lẹ́bánónì sì rọ.
Ayé á ru sókè nítorí ojú rẹ̀,
Àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tó ń gbé orí rẹ̀.+
6 Ta ló lè dúró nígbà tó bá ń bínú?+
Ta ló sì lè fara da ooru ìbínú rẹ̀?+
Yóò tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná,
Àwọn àpáta á sì fọ́ sí wẹ́wẹ́ nítorí rẹ̀.
7 Jèhófà jẹ́ ẹni rere,+ odi agbára ní ọjọ́ wàhálà.+
Ó sì mọ* àwọn tó ń wá ibi ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀.+
8 Àkúnya omi ló máa fi pa Nínéfè* run,
Òkùnkùn á sì lé àwọn ọ̀tá rẹ̀.
9 Kí lẹ rò pé ẹ lè ṣe sí Jèhófà?
Ó ń fa ìparun yán-án yán-án.
Wàhálà kò ní dìde lẹ́ẹ̀kejì.+
10 Wọ́n ṣù pọ̀ mọ́ra bí ẹ̀gún,
Wọ́n sì dà bí àwọn tó mu ọtí bíà yó;*
Ṣùgbọ́n iná á jó wọn run bí àgékù pòròpórò gbígbẹ.
11 Ẹni tó ń gbèrò ibi sí Jèhófà máa jáde wá láti ọ̀dọ̀ rẹ,
Á sì máa fúnni ní ìmọ̀ràn tí kò dáa.
12 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní agbára, tí wọ́n sì pọ̀ gan-an,
Síbẹ̀, a máa gé wọn lulẹ̀, wọ́n á sì kọjá lọ.*
Mo ti fìyà jẹ ọ́* tẹ́lẹ̀, àmọ́ mi ò ní fìyà jẹ ọ́ mọ́.
13 Nítorí náà, màá ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ,+
Màá sì já ìdè rẹ sí méjì.
Màá run àwọn ère gbígbẹ́ àti ère onírin* kúrò ní ilé* àwọn ọlọ́run rẹ.
Màá gbẹ́ sàréè fún ọ torí pé mo kórìíra rẹ gan-an.’
Ṣe àwọn àjọyọ̀ rẹ,+ ìwọ Júdà, kí o sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ,
Nítorí ẹni tí kò ní láárí kò tún ní gba àárín rẹ kọjá mọ́.
Ṣe ni yóò pa run pátápátá.”
Máa ṣọ́ àwọn ibi olódi.
Máa ṣọ́ ọ̀nà.
Gbára dì,* kí o sì sa gbogbo agbára rẹ.
2 Nítorí Jèhófà yóò dá ògo Jékọ́bù pa dà,
Yóò dá a pa dà sí ògo Ísírẹ́lì,
Nítorí àwọn apanirun ti pa wọ́n run;+
Wọ́n sì ti pa àwọn ọ̀mùnú wọn run.
3 Apata àwọn ọkùnrin rẹ̀ alágbára ti di pupa,
Aṣọ àwọn jagunjagun rẹ̀ ti rẹ̀ dòdò.
Àwọn irin tí wọ́n dè mọ́ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ń kọ mànà bí iná
Ní ọjọ́ tó ń múra ogun sílẹ̀,
Ó sì ń ju àwọn ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi igi júnípà ṣe fìrìfìrì.
4 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń sáré àsápajúdé ní ojú ọ̀nà.
Wọ́n ń sáré sókè-sódò ní àwọn ojúde ìlú.
Wọ́n ń mọ́lẹ̀ yòò bí iná ògùṣọ̀, wọ́n sì ń kọ mànà bíi mànàmáná.
5 Ó máa pe àwọn ọ̀gágun rẹ̀.
Wọ́n á kọsẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ.
Wọ́n á sáré lọ sí ibi ògiri rẹ̀;
Wọ́n á sì gbé ohun ìdènà kalẹ̀.
7 A ti pá a láṣẹ:* Wọ́n ti tú u sí ìhòòhò,
Wọ́n gbé e lọ, àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ dárò rẹ̀;
Wọ́n ń ké bí àdàbà bí wọ́n ṣe ń fọwọ́ lu àyà* wọn.
8 Láti ọjọ́ tí Nínéfè+ ti wà ló ti dà bí adágún omi,
Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ń sá lọ.
“Ẹ dúró! Ẹ dúró!”
Àmọ́ kò sí ẹni tó yíjú pa dà.+
9 Ẹ kó fàdákà, ẹ kó wúrà!
Àwọn ìṣúra rẹ̀ kò lópin.
Onírúurú ohun iyebíye ló kún inú rẹ̀.
10 Ìlú náà ti ṣófo, ó ti di ahoro, ó sì ti pa run!+
Ìbẹ̀rù ti jẹ́ kí ọkàn wọn domi, orúnkún wọn ń gbọ̀n, gbogbo ara ń ro wọ́n;
Gbogbo ojú wọn sì pọ́n.
11 Ibo ni àwọn kìnnìún ń gbé,+ níbi tí àwọn ọmọ kìnnìún* ti ń jẹun,
Níbi tí kìnnìún ti ń kó ọmọ rẹ̀ jáde,
Tí ẹnì kankan ò sì dẹ́rù bà wọ́n?
12 Kìnnìún ń fa ọ̀pọ̀ ẹran ya fún àwọn ọmọ rẹ̀
Ó sì ń fún ẹran lọ́rùn pa fún àwọn abo rẹ̀.
Ó kó ẹran tí ó pa kún inú ihò rẹ̀,
Àti èyí tó fà ya kún ibùgbé rẹ̀.
13 “Wò ó! Mo dojú ìjà kọ ọ́,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,+
“Màá mú kí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ jóná pátápátá,+
Idà yóò sì pa àwọn ọmọ kìnnìún* rẹ run.
Mi ò ní jẹ́ kí o mú àwọn èèyàn bí ẹran mọ́ ní ayé,
A kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn òjíṣẹ́ rẹ mọ́.”+
3 Ìlú tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ gbé!
Ẹ̀tàn àti ìjanilólè pọ̀ jọjọ nínú rẹ̀.
Kò sígbà tí kì í rí nǹkan mú!
2 Ìró pàṣán ń dún, àgbá kẹ̀kẹ́ sì ń rọ́ gìrìgìrì,
Ẹṣin ń bẹ́ lọ, kẹ̀kẹ́ ẹṣin sì ń pariwo.
3 Agẹṣin ń gun ẹṣin, idà ń kọ mànà, ọ̀kọ̀ sì ń dán yinrin,
Àwọn tí wọ́n pa sùn lọ bẹẹrẹ, àwọn òkú sì wà ní òkìtì-òkìtì
Àwọn òkú náà kò lóǹkà.
Bí àwọn èèyàn náà ṣe ń rìn lọ, ṣe ni wọ́n ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú.
4 Ó jẹ́ nítorí ọ̀pọ̀ ìṣekúṣe aṣẹ́wó náà,
Ẹni tó rẹwà, tó sì fani mọ́ra, ìyálóde àwọn oníṣẹ́ àjẹ́,
Ẹni tó ń fi iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ̀ mú àwọn orílẹ̀-èdè, tó sì ń fi iṣẹ́ àjẹ́ rẹ̀ mú àwọn ìdílé.
5 “Wò ó! Mo dojú ìjà kọ ọ́,”* ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,+
“Màá ká aṣọ rẹ bò ọ́ lójú;
Màá jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè rí ìhòòhò rẹ,
Àwọn ìjọba á sì rí ìtìjú rẹ.
6 Màá da ẹ̀gbin sí ọ lára
Màá sọ ẹ́ di ohun ìkórìíra;
Màá sì jẹ́ kí o di ìran àpéwò.+
Ta ló máa bá a kẹ́dùn?’
Ibo ni màá ti rí àwọn olùtùnú fún ọ?
8 Ṣé o sàn ju No-ámónì* lọ,+ tó jókòó sí ẹ̀gbẹ́ ipa odò Náílì?+
Omi ló yí i ká;
Òkun ni ọrọ̀ rẹ̀, òkun sì ni ògiri rẹ̀.
9 Etiópíà àti Íjíbítì ló fún un ní agbára tí kò láàlà.
Pútì+ àti àwọn ará Líbíà sì ni olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.+
10 Síbẹ̀, ó dèrò ìgbèkùn;
Ó sì lọ sí oko ẹrú.+
Wọ́n fọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ náà mọ́lẹ̀ ní gbogbo oríta* ojú ọ̀nà.
Wọ́n sì ṣẹ́ kèké lé àwọn ọkùnrin rẹ̀ ọlọ́lá,
Gbogbo èèyàn pàtàkì inú rẹ̀ ni wọ́n sì ti dè ní ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀.
11 Ìwọ náà á mutí yó;+
Wàá lọ fara pa mọ́.
Wàá sì wá ibi ààbò lọ́dọ̀ ọ̀tá rẹ.
12 Gbogbo ibi olódi rẹ dà bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tó ní àkọ́pọ́n èso;
Tí a bá mì í jìgìjìgì, àwọn èso náà máa já bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun.
13 Wò ó! Àwọn ọmọ ogun rẹ dà bí obìnrin ní àárín rẹ.
Àwọn ẹnubodè ilẹ̀ rẹ á ṣí sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ.
Iná á sì jó àwọn ọ̀pá ìdábùú ẹnubodè rẹ run.
14 Pọn omi sílẹ̀ de ìgbà tí ogun máa ká ọ mọ́!+
Mú kí àwọn ibi olódi rẹ lágbára.
Bọ́ sínú ẹrẹ̀, kí o sì fi ẹsẹ̀ tẹ amọ̀;
Di ohun tí wọ́n fi ń yọ bíríkì mú gírígírí.
15 Àní ibẹ̀ ni iná á ti jó ọ run.
Idà yóò gé ọ lulẹ̀.+
Yóò jẹ ọ́ run bí àwọn ọmọ eéṣú ṣe ń jẹ nǹkan run.+
Sọ ara rẹ di púpọ̀ bí àwọn ọmọ eéṣú!
Àní, sọ ara rẹ di púpọ̀ bí àwọn eéṣú!
16 O ti mú kí àwọn oníṣòwò rẹ pọ̀ ju àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ.
Eéṣú tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà bọ́ awọ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fò lọ.
17 Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ dà bí eéṣú,
Àwọn ọ̀gágun rẹ sì dà bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ eéṣú.
Wọ́n sá sínú ọgbà ẹran tí a fi òkúta ṣe ní ọjọ́ òtútù,
Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn ràn, wọ́n fò lọ;
Kò sì sẹ́ni tó mọ ibi tí wọ́n wà.
18 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn rẹ ń tòògbé, ìwọ ọba Ásíríà;
Àwọn èèyàn pàtàkì rẹ wà ní ibùgbé wọn.
Àwọn èèyàn rẹ ti fọ́n ká sórí àwọn òkè,
Kò sì sẹ́ni tó máa kó wọn jọ.+
19 Ìwọ kò ní rí ìtura nínú àjálù rẹ.
Ọgbẹ́ rẹ ti kọjá èyí tó ṣeé wò sàn.
Gbogbo àwọn tó bá gbọ́ ìròyìn nípa rẹ máa pàtẹ́wọ́;+
Àbí ta ni kò tíì fara gbá nínú ìwà ìkà tí ò ń hù láìdáwọ́ dúró?”+
Ó túmọ̀ sí “Olùtùnú.”
Tàbí “ń tọ́jú.”
Ní Héb., “àyè rẹ̀.”
Tàbí “bíà tí wọ́n fi wíìtì ṣe.”
Tàbí kó jẹ́, “yóò sì là á kọjá.”
Ìyẹn, “Júdà.”
Ìyẹn, “Ásíríà.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Ìyẹn, Nínéfè.
Ní Héb., “Fún ìgbáròkó lókun.”
Tàbí “á sì yọ́.”
Tàbí “pinnu rẹ̀.”
Ní Héb., “ọkàn.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Ìyẹn, Nínéfè.
Ìyẹn, Tíbésì.
Ní Héb., “ìkóríta.”