ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́
1 Lẹ́yìn tí Jóṣúà kú,+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà pé: “Ta ló máa kọ́kọ́ lọ bá àwọn ọmọ Kénáánì jagun nínú wa?” 2 Jèhófà fèsì pé: “Júdà ni kó lọ.+ Wò ó! Màá fi* ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.” 3 Júdà wá sọ fún Síméónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé: “Jẹ́ ká jọ lọ sí ilẹ̀ tí wọ́n fún mi,*+ ká lọ bá àwọn ọmọ Kénáánì jà. Èmi náà á sì bá ọ lọ sí ilẹ̀ tí wọ́n fún ọ.” Torí náà, Síméónì tẹ̀ lé e lọ.
4 Nígbà tí Júdà lọ, Jèhófà fi àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì lé wọn lọ́wọ́,+ wọ́n sì ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin ní Bésékì. 5 Wọ́n rí Adoni-bésékì ní Bésékì, wọ́n bá a jà níbẹ̀, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì+ àti àwọn Pérísì.+ 6 Nígbà tí Adoni-bésékì sá lọ, wọ́n lé e bá, wọ́n mú un, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ rẹ̀ àti ti ẹsẹ̀ rẹ̀. 7 Adoni-bésékì wá sọ pé: “Àádọ́rin (70) ọba ni mo ti gé àtàǹpàkò ọwọ́ àti ti ẹsẹ̀ wọn, tí wọ́n sì ń ṣa oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Ohun tí mo ṣe gẹ́lẹ́ ni Ọlọ́run fi san mí lẹ́san.” Lẹ́yìn náà, wọ́n mú un wá sí Jerúsálẹ́mù,+ ó sì kú síbẹ̀.
8 Bákan náà, àwọn ọkùnrin Júdà bá Jerúsálẹ́mù+ jà, wọ́n sì gbà á; wọ́n fi idà pa á run, wọ́n sì dáná sun ìlú náà. 9 Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Júdà lọ bá àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé agbègbè olókè jà, wọ́n tún bá Négébù àti Ṣẹ́fẹ́là+ jà. 10 Júdà tún lọ bá àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ní Hébúrónì jà (Kiriati-ábà ni Hébúrónì ń jẹ́ tẹ́lẹ̀), wọ́n sì pa Ṣéṣáì, Áhímánì àti Tálímáì.+
11 Wọ́n kúrò níbẹ̀ lọ bá àwọn tó ń gbé Débírì+ jà. (Kiriati-séférì+ ni Débírì ń jẹ́ tẹ́lẹ̀.) 12 Kélẹ́bù+ wá sọ pé: “Ẹni tó bá pa Kiriati-séférì run, tó sì gbà á, màá fún un ní Ákúsà ọmọ mi pé kó fi ṣe aya.”+ 13 Ótíníẹ́lì+ ọmọ Kénásì,+ àbúrò Kélẹ́bù sì gbà á. Torí náà, ó fún un ní Ákúsà ọmọ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya. 14 Nígbà tí ọmọbìnrin náà ń lọ sílé, ó rọ ọmọkùnrin náà pé kó tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ bàbá òun. Ọmọbìnrin náà wá sọ̀ kalẹ̀ látorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀.* Kélẹ́bù sì bi í pé: “Kí lo fẹ́?” 15 Ó sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, bù kún mi, o ti fún mi ní ilẹ̀ kan ní gúúsù;* tún fún mi ní Guloti-máímù.”* Torí náà, Kélẹ́bù fún un ní Gúlótì Òkè àti Gúlótì Ìsàlẹ̀.
16 Àtọmọdọ́mọ àwọn Kénì,+ tó jẹ́ bàbá ìyàwó Mósè+ pẹ̀lú àwọn èèyàn Júdà wá láti ìlú ọlọ́pẹ+ sí aginjù Júdà, tó wà ní gúúsù Árádì.+ Wọ́n lọ síbẹ̀, wọ́n sì ń gbé láàárín àwọn èèyàn náà.+ 17 Àmọ́ Júdà ń tẹ̀ lé Síméónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ, wọ́n gbéjà ko àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé Séfátì, wọ́n sì pa wọ́n run.+ Wọ́n wá pe orúkọ ìlú náà ní Hóómà.*+ 18 Nígbà náà, Júdà gba Gásà+ àti agbègbè rẹ̀, Áṣíkẹ́lónì+ àti agbègbè rẹ̀ pẹ̀lú Ẹ́kírónì+ àti agbègbè rẹ̀. 19 Jèhófà wà pẹ̀lú Júdà, wọ́n sì gba agbègbè olókè náà, àmọ́ wọn ò lè lé àwọn tó ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà kúrò, torí pé wọ́n ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin.*+ 20 Wọ́n fún Kélẹ́bù ní Hébúrónì, bí Mósè ṣe ṣèlérí,+ ó sì lé àwọn ọmọ Ánákì+ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kúrò níbẹ̀.
21 Àmọ́ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ò lé àwọn ará Jébúsì tó ń gbé Jerúsálẹ́mù kúrò, torí náà, àwọn ará Jébúsì ṣì ń bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì gbé ní Jerúsálẹ́mù títí dòní.+
22 Ìgbà yẹn ni ilé Jósẹ́fù+ lọ bá Bẹ́tẹ́lì jà, Jèhófà sì wà pẹ̀lú wọn.+ 23 Nígbà tí ilé Jósẹ́fù ń ṣe amí Bẹ́tẹ́lì (bẹ́ẹ̀ sì rèé, Lúsì+ ni ìlú náà ń jẹ́ tẹ́lẹ̀), 24 àwọn amí náà rí ọkùnrin kan tó ń jáde lọ látinú ìlú náà. Torí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, fi ọ̀nà tí a máa gbà wọnú ìlú yìí hàn wá, a sì máa ṣe ọ́ dáadáa.”* 25 Ọkùnrin náà wá fi ọ̀nà tí wọ́n máa gbà wọnú ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n sì fi idà pa ìlú náà run, àmọ́ wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ sí.+ 26 Ọkùnrin náà lọ sí ilẹ̀ àwọn ọmọ Hétì, ó kọ́ ìlú kan síbẹ̀, ó sì pè é ní Lúsì, orúkọ ìlú náà nìyẹn títí dòní.
27 Mánásè ò gba Bẹti-ṣéánì àti àwọn àrọko rẹ̀,* Táánákì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Dórì àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Íbíléámù àti àwọn àrọko+ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé Mẹ́gídò àti àwọn àrọko rẹ̀. Àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbé ní ilẹ̀ yìí. 28 Nígbà tí Ísírẹ́lì lágbára sí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fipá kó àwọn ọmọ Kénáánì ṣiṣẹ́ àṣekára,+ àmọ́ wọn ò lé wọn kúrò pátápátá.+
29 Éfúrémù náà ò lé àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ní Gésérì kúrò. Àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbé láàárín wọn ní Gésérì.+
30 Sébúlúnì ò lé àwọn tó ń gbé Kítírónì kúrò àti àwọn tó ń gbé Náhálólì.+ Àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbé láàárín wọn, wọ́n sì ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́ àṣekára.+
31 Áṣérì ò lé àwọn tó ń gbé Ákò kúrò, kò sì lé àwọn tó ń gbé Sídónì,+ Álábù, Ákísíbù,+ Hélíbà, Áfíkì+ àti Réhóbù+ kúrò. 32 Àwọn ọmọ Áṣérì ṣì ń gbé láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ilẹ̀ náà, torí pé wọn ò lé wọn kúrò.
33 Náfútálì ò lé àwọn tó ń gbé Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti àwọn tó ń gbé Bẹti-ánátì+ kúrò, wọ́n ṣì ń gbé láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ilẹ̀ náà.+ Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fipá kó àwọn tó ń gbé Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti Bẹti-ánátì ṣiṣẹ́ àṣekára.
34 Àwọn Ámórì sé àwọn ọmọ Dánì mọ́ agbègbè olókè, wọn ò jẹ́ kí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀.+ 35 Torí náà, àwọn Ámórì ṣì ń gbé ní Òkè Hérésì, Áíjálónì+ àti Ṣáálíbímù.+ Àmọ́ nígbà tí agbára* ilé Jósẹ́fù pọ̀ sí i,* wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fipá kó wọn ṣiṣẹ́ àṣekára. 36 Ilẹ̀ àwọn Ámórì bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ákírábímù,+ láti Sẹ́ẹ́là sókè.
2 Áńgẹ́lì Jèhófà+ wá kúrò ní Gílígálì+ lọ sí Bókímù, ó sì sọ pé: “Mo mú yín kúrò ní Íjíbítì wá sí ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá+ yín. Bákan náà, mo sọ pé, ‘Mi ò ní da májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín láé.+ 2 Àmọ́ kí ẹ má ṣe bá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí+ dá májẹ̀mú, kí ẹ wó àwọn pẹpẹ+ wọn.’ Àmọ́ ẹ ò fetí sí ohùn mi.+ Kí ló dé tí ẹ ṣe báyìí? 3 Torí náà ni mo ṣe sọ pé, ‘Mi ò ní lé wọn kúrò níwájú yín,+ wọ́n máa di ìdẹkùn fún yín,+ àwọn ọlọ́run wọn á sì tàn yín lọ.’”+
4 Nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún kíkankíkan. 5 Torí náà, wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Bókímù,* wọ́n sí rúbọ sí Jèhófà níbẹ̀.
6 Nígbà tí Jóṣúà ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà síbi ogún wọn kí wọ́n lè gba ilẹ̀ náà.+ 7 Àwọn èèyàn náà ṣì ń sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ ayé àwọn àgbààgbà tí ẹ̀mí wọn gùn ju ti Jóṣúà lọ, tí wọ́n sì ti rí gbogbo ohun tó kàmàmà tí Jèhófà ṣe nítorí Ísírẹ́lì.+ 8 Jóṣúà ọmọ Núnì, ìránṣẹ́ Jèhófà, wá kú lẹ́ni àádọ́fà (110) ọdún.+ 9 Torí náà, wọ́n sin ín sí ilẹ̀ tó jogún ní Timunati-hérésì,+ èyí tó wà ní agbègbè olókè Éfúrémù, ní àríwá Òkè Gááṣì.+ 10 Gbogbo ìran yẹn ni wọ́n kó jọ pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn,* ìran míì sì bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn wọn tí kò mọ Jèhófà, tí kò sì mọ ohun tó ṣe fún Ísírẹ́lì.
11 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, wọ́n sì sin* àwọn Báálì.+ 12 Bí wọ́n ṣe fi Jèhófà, Ọlọ́run àwọn bàbá wọn sílẹ̀ nìyẹn, ẹni tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Wọ́n wá tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí wọn ká,+ wọ́n forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n sì múnú bí Jèhófà.+ 13 Wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì sin Báálì àti àwọn ère Áṣítórétì.+ 14 Jèhófà wá bínú gidigidi sí Ísírẹ́lì, torí náà, ó fi wọ́n lé àwọn tó ń kóni lẹ́rù lọ́wọ́.+ Ó fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá tó yí wọn ká,+ apá wọn ò sì ká àwọn ọ̀tá wọn mọ́.+ 15 Ibikíbi tí wọ́n bá lọ ni ọwọ́ Jèhófà ti ń fìyà jẹ wọ́n, tó ń mú àjálù bá wọn,+ bí Jèhófà ṣe sọ àti bí Jèhófà ṣe búra fún wọn,+ ìdààmú sì bá wọn gidigidi.+ 16 Torí náà, Jèhófà máa ń yan àwọn onídàájọ́ tó máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń kó wọn lẹ́rù.+
17 Àmọ́ wọn ò fetí sí àwọn onídàájọ́ náà pàápàá, wọ́n tún máa ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run míì,* wọ́n sì máa ń forí balẹ̀ fún wọn. Kò pẹ́ tí wọ́n fi yà kúrò ní ọ̀nà tí àwọn baba ńlá wọn rìn, àwọn tó tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà.+ Wọn ò ṣe bíi tiwọn. 18 Nígbàkigbà tí Jèhófà bá yan àwọn onídàájọ́ fún wọn,+ Jèhófà máa ń wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, ó sì máa ń gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo ọjọ́ tí onídàájọ́ náà bá fi wà; Jèhófà ṣàánú wọn*+ torí pé àwọn tó ń ni wọ́n lára+ àtàwọn tó ń fìyà jẹ wọ́n mú kí wọ́n máa kérora.
19 Àmọ́ tí onídàájọ́ náà bá kú, wọ́n á tún bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ìbàjẹ́ tó ju ti àwọn bàbá wọn lọ ní ti pé, wọ́n á máa tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, wọ́n á máa sìn wọ́n, wọ́n á sì máa forí balẹ̀ fún wọn.+ Wọn ò fi ìwà wọn àti agídí wọn sílẹ̀. 20 Níkẹyìn, Jèhófà bínú gidigidi sí Ísírẹ́lì,+ ó sì sọ pé: “Torí pé orílẹ̀-èdè yìí ti da májẹ̀mú mi+ tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò sì fetí sí mi,+ 21 mi ò ní lé ìkankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò níwájú wọn, àwọn tí Jóṣúà fi sílẹ̀ nígbà tó kú.+ 22 Èyí máa jẹ́ kí n mọ̀ bóyá Ísírẹ́lì máa pa ọ̀nà Jèhófà mọ́ + nípa rírìn nínú rẹ̀ bíi ti àwọn bàbá wọn.” 23 Torí náà, Jèhófà fi àwọn orílẹ̀-èdè yìí sílẹ̀. Kò tètè lé wọn kúrò, kò sì fi wọ́n lé Jóṣúà lọ́wọ́.
3 Èyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà fi sílẹ̀, láti dán gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wò, àwọn tí ogun kankan ò ṣẹlẹ̀ lójú wọn rí ní Kénáánì+ 2 (torí kí ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kàn lè mọ bí ogun ṣe rí, àwọn tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ sí rí): 3 àwọn alákòóso Filísínì+ márààrún àti gbogbo àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Sídónì+ àti àwọn Hífì+ tó ń gbé Òkè Lẹ́bánónì+ láti Òkè Baali-hámónì títí dé Lebo-hámátì.*+ 4 Àwọn la fi dán Ísírẹ́lì wò, láti mọ̀ bóyá Ísírẹ́lì á máa tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà tó fún àwọn bàbá wọn nípasẹ̀ Mósè.+ 5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ń gbé láàárín àwọn ọmọ Kénáánì,+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì. 6 Wọ́n ń fi àwọn ọmọbìnrin wọn ṣe aya, wọ́n sì ń fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní àwọn ọmọbìnrin tiwọn, wọ́n tún ń sin àwọn ọlọ́run wọn.+
7 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, wọ́n gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin àwọn Báálì+ àti àwọn òpó òrìṣà.*+ 8 Ni Jèhófà bá bínú gidigidi sí Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n lé Kuṣani-ríṣátáímù ọba Mesopotámíà* lọ́wọ́. Ọdún mẹ́jọ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi sin Kuṣani-ríṣátáímù. 9 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,+ Jèhófà yan ẹnì kan tó máa gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀,+ ìyẹn Ótíníẹ́lì+ ọmọ Kénásì, àbúrò Kélẹ́bù. 10 Ẹ̀mí Jèhófà bà lé e,+ ó sì di onídàájọ́ Ísírẹ́lì. Nígbà tó lọ jagun, Jèhófà fi Kuṣani-ríṣátáímù ọba Mesopotámíà* lé e lọ́wọ́, ó sì ṣẹ́gun Kuṣani-ríṣátáímù. 11 Àlàáfíà wá wà ní ilẹ̀ náà* fún ogójì (40) ọdún. Lẹ́yìn náà, Ótíníẹ́lì ọmọ Kénásì wá kú.
12 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà.+ Torí náà, Jèhófà jẹ́ kí Ẹ́gílónì ọba Móábù+ lágbára lórí Ísírẹ́lì, torí wọ́n ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà. 13 Bákan náà, ó kó àwọn ọmọ Ámónì+ àti àwọn ọmọ Ámálékì+ lọ bá wọn jà. Wọ́n gbéjà ko Ísírẹ́lì, wọ́n sì gba ìlú ọlọ́pẹ.+ 14 Ọdún méjìdínlógún (18)+ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi sin Ẹ́gílónì ọba Móábù. 15 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,+ torí náà, Jèhófà yan ẹnì kan tó máa gbà wọ́n sílẹ̀,+ ìyẹn Éhúdù+ ọmọ Gérà, ọmọ Bẹ́ńjámínì,+ ọkùnrin tó ń lo ọwọ́ òsì.+ Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ìṣákọ́lẹ̀* rán an sí Ẹ́gílónì ọba Móábù. 16 Àmọ́ Éhúdù ti ṣe idà olójú méjì kan fún ara rẹ̀, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* kan, ó sì dè é mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún lábẹ́ aṣọ rẹ̀. 17 Ó wá fún Ẹ́gílónì ọba Móábù ní ìṣákọ́lẹ̀ náà. Ẹ́gílónì sanra gan-an.
18 Nígbà tí Éhúdù fi ìṣákọ́lẹ̀ náà jíṣẹ́ tán, ó ní kí àwọn tó gbé ìṣákọ́lẹ̀ náà máa lọ. 19 Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ibi àwọn ère gbígbẹ́* ní Gílígálì,+ òun nìkan pa dà, ó sì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ àṣírí kan wà tí mo fẹ́ sọ fún ọ, ìwọ ọba.” Ọba wá sọ pé: “Ẹ dákẹ́!” Ni gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 20 Torí náà, Éhúdù lọ bá a níbi tó dá jókòó sí nínú yàrá tó tura lórí òrùlé rẹ̀. Éhúdù wá sọ pé: “Ọlọ́run rán mi sí ọ.” Ó wá dìde lórí ìtẹ́* rẹ̀. 21 Ni Éhúdù bá fi ọwọ́ òsì rẹ̀ fa idà náà yọ ní itan rẹ̀ ọ̀tún, ó sì fi gún un ní ikùn. 22 Idà náà wọlé tòun ti èèkù rẹ̀, ọ̀rá sì bo idà náà torí kò fa idà náà yọ ní ikùn rẹ̀, ìgbẹ́ sì tú jáde. 23 Éhúdù wá gba ibi àbáwọlé* jáde, ó pa ilẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà dé nígbà tó jáde, ó sì tì í pa. 24 Lẹ́yìn tó lọ, àwọn ìránṣẹ́ pa dà wá, wọ́n sì rí i pé ilẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà wà ní títì pa. Torí náà, wọ́n sọ pé: “Bóyá ó ń tura* nínú yàrá tó tura nínú lọ́hùn-ún.” 25 Wọ́n wá dúró títí ó fi sú wọn, àmọ́ nígbà tí wọ́n rí i pé síbẹ̀, kò ṣí ilẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí i, ni wọ́n bá rí òkú ọ̀gá wọn nílẹ̀!
26 Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi ń dúró, Éhúdù ti sá lọ, ó kọjá ibi àwọn ère gbígbẹ́,*+ ó sì dé Séírà láìséwu. 27 Nígbà tó débẹ̀, ó fun ìwo+ ní agbègbè olókè Éfúrémù;+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì sọ̀ kalẹ̀ kúrò ní agbègbè olókè náà, òun ló ṣáájú wọn. 28 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ tẹ̀ lé mi, torí Jèhófà ti fi àwọn ọ̀tá yín, àwọn ọmọ Móábù, lé yín lọ́wọ́.” Torí náà, wọ́n tẹ̀ lé e, wọ́n sì gba ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá ní odò Jọ́dánì mọ́ àwọn ọmọ Móábù lọ́wọ́, wọn ò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá. 29 Nígbà yẹn, wọ́n pa nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn ọmọ Móábù,+ alágbára ni gbogbo wọn, wọ́n sì lákíkanjú; àmọ́ ìkankan nínú wọn ò yè bọ́.+ 30 Ọjọ́ yẹn ni Ísírẹ́lì ṣẹ́gun Móábù; àlàáfíà wá wà ní ilẹ̀ náà* fún ọgọ́rin (80) ọdún.+
31 Lẹ́yìn Éhúdù ni Ṣámúgárì+ ọmọ Ánátì, tó fi ọ̀pá tí wọ́n fi ń da màlúù+ pa ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin Filísínì;+ òun náà gba Ísírẹ́lì sílẹ̀.
4 Àmọ́ lẹ́yìn tí Éhúdù kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà.+ 2 Torí náà, Jèhófà fi wọ́n lé ọwọ́ Jábínì ọba Kénáánì,+ tó jọba ní Hásórì. Sísérà ni olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ó sì ń gbé ní Háróṣétì+ ti àwọn orílẹ̀-èdè.* 3 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà,+ torí pé Jábínì* ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin,*+ ogún (20) ọdún ló sì fi fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gidigidi.+
4 Nígbà yẹn, Dèbórà, wòlíì obìnrin+ tó jẹ́ ìyàwó Lápídótù ń ṣe ìdájọ́ ní Ísírẹ́lì. 5 Abẹ́ igi ọ̀pẹ Dèbórà ló máa ń jókòó sí, láàárín Rámà+ àti Bẹ́tẹ́lì,+ ní agbègbè olókè Éfúrémù; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kó ẹjọ́ wọn lọ bá a. 6 Ó ránṣẹ́ sí Bárákì+ ọmọ Ábínóámù láti Kedeṣi-náfútálì,+ ó sì sọ fún un pé: “Ṣebí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti pàṣẹ? ‘Lọ sí* Òkè Tábórì, kí o sì kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin dání látinú àwọn ọmọ Náfútálì àti Sébúlúnì. 7 Màá mú Sísérà, olórí àwọn ọmọ ogun Jábínì wá bá ọ, tòun ti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wá sí odò* Kíṣónì,+ màá sì fi lé ọ lọ́wọ́.’”+
8 Ni Bárákì bá sọ fún un pé: “Tí o bá máa tẹ̀ lé mi, màá lọ, àmọ́ tó ò bá tẹ̀ lé mi, mi ò ní lọ.” 9 Dèbórà fèsì pé: “Ó dájú pé màá bá ọ lọ. Àmọ́ o ò ní gba ògo nínú ogun tí o fẹ́ lọ jà yìí, torí obìnrin ni Jèhófà máa fi Sísérà+ lé lọ́wọ́.” Dèbórà wá gbéra, ó sì tẹ̀ lé Bárákì lọ sí Kédéṣì.+ 10 Bárákì pe Sébúlúnì àti Náfútálì+ sí Kédéṣì, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin sì tẹ̀ lé e. Dèbórà náà bá a lọ.
11 Ó ṣẹlẹ̀ pé Hébà ará Kénì ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn Kénì,+ àwọn àtọmọdọ́mọ Hóbábù, bàbá ìyàwó+ Mósè, ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí tòsí igi ńlá ní Sáánánímù, tó wà ní Kédéṣì.
12 Sísérà wá gbọ́ pé Bárákì ọmọ Ábínóámù ti lọ sórí Òkè Tábórì.+ 13 Ojú ẹsẹ̀ ni Sísérà ṣètò gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin* àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀-èdè kí wọ́n lè lọ sí odò* Kíṣónì.+ 14 Dèbórà wá sọ fún Bárákì pé: “Gbéra, torí òní yìí ni Jèhófà máa fi Sísérà lé ọ lọ́wọ́. Ṣebí Jèhófà ń ṣáájú rẹ lọ?” Bárákì sì sọ̀ kalẹ̀ láti orí Òkè Tábórì pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin tó ń tẹ̀ lé e. 15 Jèhófà wá mú kí nǹkan dà rú mọ́ Sísérà lójú+ pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ níwájú idà Bárákì. Nígbà tó yá, Sísérà sọ̀ kalẹ̀ nínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì sá lọ. 16 Bárákì lé àwọn kẹ̀kẹ́ ogun náà àti àwọn ọmọ ogun títí dé Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀-èdè. Bí wọ́n ṣe fi idà pa gbogbo àwọn ọmọ ogun Sísérà nìyẹn; ìkankan nínú wọn ò ṣẹ́ kù.+
17 Àmọ́ Sísérà sá lọ sí àgọ́ Jáẹ́lì+ ìyàwó Hébà+ ará Kénì, torí àlàáfíà wà láàárín Jábínì+ ọba Hásórì àti ìdílé Hébà ará Kénì. 18 Jáẹ́lì sì jáde wá pàdé Sísérà, ó sọ fún un pé: “Wọlé, olúwa mi, máa bọ̀ níbí. Má bẹ̀rù.” Ló bá wọlé sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ tó nípọn bò ó. 19 Ó wá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní omi díẹ̀ mu, torí òùngbẹ ń gbẹ mí.” Ni Jáẹ́lì bá ṣí ìgò awọ kan tí wọ́n rọ wàrà sí, ó sì fún un mu,+ ó wá tún fi aṣọ bò ó. 20 Sísérà sọ fún Jáẹ́lì pé: “Dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́, tí ẹnikẹ́ni bá sì wá bi ọ́ pé, ‘Ṣé ọkùnrin kankan wà níbí?’ kí o sọ pé, ‘Rárá!’”
21 Àmọ́ Jáẹ́lì ìyàwó Hébà mú èèkàn àgọ́, ó sì mú òòlù dání. Nígbà tí ọkùnrin náà ti sùn lọ fọnfọn, tó sì ti rẹ̀ ẹ́, Jáẹ́lì yọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó gbá èèkàn àgọ́ náà wọnú ẹ̀bátí rẹ̀, ó gbá a wọlẹ̀, ọkùnrin náà sì kú.+
22 Bárákì wá Sísérà débẹ̀, Jáẹ́lì sì jáde wá pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé: “Máa bọ̀, jẹ́ kí n fi ọkùnrin tí ò ń wá hàn ọ́.” Bárákì bá tẹ̀ lé e wọlé, ó sì rí òkú Sísérà nílẹ̀, pẹ̀lú èèkàn àgọ́ tí Jáẹ́lì gbá wọnú ẹ̀bátí rẹ̀.
23 Ọjọ́ yẹn ni Ọlọ́run mú kí apá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ká+ Jábínì ọba Kénáánì. 24 Ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì túbọ̀ ń ran Jábínì ọba Kénáánì,+ títí wọ́n fi pa Jábínì ọba Kénáánì.+
5 Ní ọjọ́ yẹn, Dèbórà+ àti Bárákì+ ọmọ Ábínóámù kọ orin+ yìí, wọ́n ní:
3 Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọba! Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ẹ̀yin aláṣẹ!
Jèhófà ni màá kọrin sí.
Màá fi orin yin* Jèhófà,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+
4 Jèhófà, nígbà tí o jáde ní Séírì,+
Nígbà tí o kúrò ní ilẹ̀ Édómù,
Ayé mì tìtì, omi ọ̀run sì ya,
Omi ya bolẹ̀ látojú ọ̀run.
6 Nígbà ayé Ṣámúgárì+ ọmọ Ánátì,
Nígbà ayé Jáẹ́lì,+ àwọn ojú ọ̀nà dá páropáro;
Ọ̀nà ẹ̀yìn ni àwọn arìnrìn-àjò ń gbà.
7 Kò sí àwọn tó ń gbé ní abúlé mọ́* ní Ísírẹ́lì;
Wọn ò sí mọ́ títí èmi, Dèbórà,+ fi dìde,
Títí mo fi di ìyá ní Ísírẹ́lì.+
A ò rí apata tàbí aṣóró kankan,
Láàárín ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ní Ísírẹ́lì.
Ẹ yin Jèhófà!
10 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláwọ̀ pupa tí a pò mọ́ yẹ́lò,
Ẹ̀yin tí ẹ jókòó sórí àwọn kápẹ́ẹ̀tì tó rẹwà,
Àti ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rìn lójú ọ̀nà,
Ẹ rò ó!
11 A gbọ́ ohùn àwọn tó ń pín omi níbi tí wọ́n ń pọn omi sí;
Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń ròyìn àwọn iṣẹ́ òdodo tí Jèhófà ṣe,
Àwọn iṣẹ́ òdodo tí àwọn ará abúlé rẹ̀ ní Ísírẹ́lì ṣe.
Àwọn èèyàn Jèhófà wá lọ sí àwọn ẹnubodè.
12 Jí, jí, ìwọ Dèbórà!+
Jí, jí, kọ orin kan!+
Dìde, Bárákì!+ Kó àwọn ẹrú rẹ lọ, ìwọ ọmọ Ábínóámù!
13 Àwọn yòókù wá bá àwọn èèyàn pàtàkì;
Àwọn èèyàn Jèhófà wá bá mi láti bá àwọn alágbára jà.
14 Éfúrémù ni wọ́n ti wá, àwọn tó wà ní àfonífojì;*
Ìwọ Bẹ́ńjámínì, wọ́n ń tẹ̀ lé ọ láàárín àwọn èèyàn rẹ.
15 Àwọn olórí láti Ísákà wà lọ́dọ̀ Dèbórà,
Bíi ti Ísákà, bẹ́ẹ̀ náà ni Bárákì.+
Wọ́n rán an pé kó fi ẹsẹ̀ rìn+ lọ sí àfonífojì.*
A yẹ ọkàn àwọn ìpín Rúbẹ́nì wò fínnífínní.
16 Kí ló dé tí o jókòó sáàárín àpò ẹrù méjì,*
Tí ò ń fetí sí wọn bí wọ́n ṣe ń fọn fèrè ape wọn fún agbo ẹran?+
A yẹ ọkàn àwọn ìpín Rúbẹ́nì wò fínnífínní.
Áṣérì jókòó gẹlẹtẹ sí etíkun,
Kò sì kúrò+ níbi tí àwọn ọkọ̀ òkun rẹ̀ ń gúnlẹ̀ sí.
18 Àwọn èèyàn tó fi ẹ̀mí wọn wewu* dójú ikú ni Sébúlúnì;
Wọn ò kó+ fàdákà kankan lójú ogun.
20 Àwọn ìràwọ̀ jà láti ọ̀run;
Wọ́n bá Sísérà jà láti ibi tí wọ́n ń gbà yí po.
O tẹ alágbára mọ́lẹ̀, ìwọ ọkàn* mi.
22 Pátákò àwọn ẹṣin wá ń kilẹ̀
Bí àwọn akọ ẹṣin rẹ̀ ṣe ń bẹ́ gìjà.+
23 Áńgẹ́lì Jèhófà sọ pé, ‘Ẹ gégùn-ún fún Mérósì,
Àní, ẹ gégùn-ún fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀,
Torí wọn ò wá ran Jèhófà lọ́wọ́,
Wọn ò tẹ̀ lé àwọn alágbára láti wá ran Jèhófà lọ́wọ́.’
24 Ẹni tí a bù kún jù lọ nínú àwọn obìnrin ni Jáẹ́lì,+
Ìyàwó Hébà+ ará Kénì;
Òun ni a bù kún jù lọ nínú àwọn obìnrin tó ń gbé inú àgọ́.
25 Omi ló béèrè; wàrà ló fún un.
Abọ́ tó níyì tí wọ́n fi ń jẹ àsè ló fi gbé wàrà dídì+ fún un.
26 Ó na ọwọ́ mú èèkàn àgọ́,
Ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù àwọn òṣìṣẹ́.
Ó sì fi kàn án mọ́ Sísérà, ó fọ́ orí rẹ̀,
Ó fọ́ ẹ̀bátí rẹ̀,+ ó dá a lu.
27 Ó wó lulẹ̀ sáàárín ẹsẹ̀ rẹ̀; ó ṣubú, kò lè dìde;
Ó wó lulẹ̀, ó sì ṣubú sáàárín ẹsẹ̀ rẹ̀;
Ibi tó wó lulẹ̀ sí, ibẹ̀ ló ṣubú sí tí wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀.
28 Obìnrin kan yọjú lójú fèrèsé,*
Ìyá Sísérà yọjú níbi fèrèsé tó ní asẹ́ onígi,
‘Kí ló dé tí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ò tíì dé?
Kí ló dé tí a ò gbúròó ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ rẹ̀?’+
29 Àwọn tó gbọ́n jù nínú àwọn obìnrin rẹ̀ pàtàkì máa dá a lóhùn;
Àní, òun náà máa tún un sọ fún ara rẹ̀ pé,
30 ‘Ó ní láti jẹ́ pé ẹrù ogun tí wọ́n kó ni wọ́n ń pín,
Ọmọbìnrin* kan, ọmọbìnrin méjì, fún jagunjagun kọ̀ọ̀kan,
Aṣọ aláró tí wọ́n kó lójú ogun fún Sísérà, aṣọ aláró tí wọ́n kó,
Aṣọ tí wọ́n kóṣẹ́ sí, aṣọ aláró, aṣọ méjì tí wọ́n kóṣẹ́ sí
Fún ọrùn àwọn tó kó ẹrù ogun.’
31 Jẹ́ kí gbogbo ọ̀tá rẹ ṣègbé,+ Jèhófà,
Àmọ́ kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ dà bí oòrùn tó ń yọ nínú ògo rẹ̀.”
Àlàáfíà sì wà ní ilẹ̀ náà* fún ogójì (40) ọdún.+
6 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ torí náà Jèhófà fi wọ́n lé Mídíánì lọ́wọ́ fún ọdún méje.+ 2 Mídíánì wá ń jọba lé Ísírẹ́lì lórí.+ Torí Mídíánì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àwọn ibi tí wọ́n lè sá pa mọ́ sí* nínú àwọn òkè, nínú àwọn ihò àti láwọn ibi tó ṣòroó dé.+ 3 Tí Ísírẹ́lì bá fún irúgbìn, àwọn ọmọ Mídíánì, Ámálékì+ àti àwọn Ará Ìlà Oòrùn+ máa wá gbógun jà wọ́n. 4 Wọ́n á pàgọ́ tì wọ́n, wọ́n á sì run èso ilẹ̀ náà títí dé Gásà, wọn ò ní ṣẹ́ oúnjẹ kankan kù fún Ísírẹ́lì, wọn ò sì ní ṣẹ́ àgùntàn, akọ màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan kù.+ 5 Wọ́n máa ń kó àwọn ẹran ọ̀sìn àtàwọn àgọ́ wọn tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ bí eéṣú+ wá, àwọn àtàwọn ràkúnmí wọn kì í níye,+ wọ́n á sì wá sí ilẹ̀ náà láti run ún. 6 Ísírẹ́lì wá tòṣì gan-an torí Mídíánì; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́.+
7 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́ torí Mídíánì,+ 8 Jèhófà rán wòlíì kan sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Mo mú yín kúrò ní Íjíbítì, mo sì tipa bẹ́ẹ̀ mú yín kúrò ní ilé ẹrú.+ 9 Mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ń fìyà jẹ yín, mo lé wọn kúrò níwájú yín, mo sì fún yín ní ilẹ̀ wọn.+ 10 Mo sọ fún yín pé: “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù àwọn ọlọ́run àwọn Ámórì tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn.”+ Àmọ́ ẹ ò fetí sí mi.’”*+
11 Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì Jèhófà wá, + ó sì jókòó sábẹ́ igi ńlá tó wà ní Ọ́fírà, èyí tó jẹ́ ti Jóáṣì ọmọ Abi-ésérì.+ Gídíónì+ ọmọ rẹ̀ ń pa àlìkámà* níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì kí àwọn ọmọ Mídíánì má bàa rí i. 12 Áńgẹ́lì Jèhófà wá yọ sí i, ó sì sọ pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ,+ ìwọ jagunjagun tó lákíkanjú.” 13 Ni Gídíónì bá sọ fún un pé: “Má bínú olúwa mi, tó bá jẹ́ pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo èyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa?+ Ibo ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ wà, èyí tí àwọn bàbá wa ròyìn ẹ̀ fún wa+ pé, ‘Ṣebí Jèhófà ló kó wa kúrò ní Íjíbítì?’+ Jèhófà ti pa wá tì+ báyìí, ó sì ti fi wá lé Mídíánì lọ́wọ́.” 14 Jèhófà kọjú sí i, ó sì sọ pé: “Lọ lo agbára tí o ní, o sì máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ Mídíánì.+ Ṣebí èmi ni mo rán ọ?” 15 Gídíónì fèsì pé: “Má bínú Jèhófà. Báwo ni màá ṣe gba Ísírẹ́lì là? Wò ó! Agbo ilé* mi ló kéré jù ní Mánásè, èmi ló sì kéré jù ní ilé bàbá mi.” 16 Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún un pé: “O máa ṣá Mídíánì balẹ̀ bíi pé ẹnì kan ṣoṣo ni wọ́n, torí màá wà pẹ̀lú rẹ.”+
17 Ó wá sọ fún un pé: “Tó bá jẹ́ pé mo ti rí ojúure rẹ, fi àmì kan hàn mí pé ìwọ lò ń bá mi sọ̀rọ̀. 18 Jọ̀ọ́, má ṣe kúrò níbí títí màá fi gbé ẹ̀bùn mi wá síwájú rẹ.”+ Ó fèsì pé: “Màá dúró síbí títí wàá fi dé.” 19 Gídíónì wá wọlé lọ, ó se ọmọ ewúrẹ́ kan, ó sì fi ìyẹ̀fun+ tó jẹ́ òṣùwọ̀n eéfà* kan ṣe búrẹ́dì aláìwú. Ó kó ẹran náà sínú apẹ̀rẹ̀, ó sì rọ omi rẹ̀ sínú ìkòkò; ó wá gbé e lọ bá a, ó sì gbé e síwájú rẹ̀ lábẹ́ igi ńlá náà.
20 Áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́ wá sọ fún un pé: “Gbé ẹran àti búrẹ́dì aláìwú náà sórí àpáta ńlá tó wà níbẹ̀ yẹn, kí o sì da omi ẹran náà jáde.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. 21 Áńgẹ́lì Jèhófà wá na orí ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kan ẹran àti búrẹ́dì aláìwú náà, iná sọ níbi àpáta náà, ó sì jó ẹran àti búrẹ́dì aláìwú+ náà run. Ni áńgẹ́lì Jèhófà bá pòórá mọ́ ọn lójú. 22 Ìgbà yẹn ni Gídíónì wá mọ̀ pé áńgẹ́lì Jèhófà+ ni.
Ojú ẹsẹ̀ ni Gídíónì sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, mo ti rí áńgẹ́lì Jèhófà lójúkojú!”+ 23 Àmọ́ Jèhófà sọ fún un pé: “Àlàáfíà ni fún ọ. Má bẹ̀rù;+ o ò ní kú.” 24 Torí náà, Gídíónì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, wọ́n sì ń pè é ní Jèhófà-ṣálómù*+ títí dòní. Ó ṣì wà ní Ọ́fírà ti àwọn ọmọ Abi-ésérì.
25 Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, Jèhófà sọ fún un pé: “Mú akọ ọmọ màlúù bàbá rẹ, akọ ọmọ màlúù kejì tó jẹ́ ọlọ́dún méje, kí o wó pẹpẹ Báálì bàbá rẹ lulẹ̀, kí o sì gé òpó òrìṣà* tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀+ lulẹ̀. 26 Tí o bá ti to òkúta láti fi mọ pẹpẹ kan fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ sórí ibi ààbò yìí, mú akọ ọmọ màlúù kejì, kí o sì fi rú ẹbọ sísun lórí àwọn igi tí o gé lára òpó òrìṣà* tí o gé lulẹ̀.” 27 Torí náà, Gídíónì mú ọkùnrin mẹ́wàá lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un gẹ́lẹ́. Àmọ́ kò lè ṣe é ní ọ̀sán torí ó bẹ̀rù agbo ilé bàbá rẹ̀ àti àwọn ọkùnrin ìlú náà gan-an, torí náà ó lọ ṣe é ní òru.
28 Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, wọ́n rí i pé wọ́n ti wó pẹpẹ Báálì lulẹ̀, wọ́n ti gé òpó òrìṣà* tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi akọ ọmọ màlúù kejì rúbọ lórí pẹpẹ tí wọ́n mọ. 29 Wọ́n bi ara wọn pé: “Ta ló dán èyí wò?” Lẹ́yìn tí wọ́n wádìí, wọ́n sọ pé: “Gídíónì ọmọ Jóáṣì ló ṣe é.” 30 Àwọn ọkùnrin ìlú náà wá sọ fún Jóáṣì pé: “Mú ọmọ rẹ jáde kó lè kú, torí pé ó wó pẹpẹ Báálì, ó sì gé òpó òrìṣà* tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lulẹ̀.” 31 Jóáṣì+ wá sọ fún gbogbo àwọn tó wá bá a pé: “Ṣé ẹ̀yin lẹ máa gbèjà Báálì ni? Àbí ẹ̀yin lẹ máa gbà á là? Ṣe la máa pa ẹnikẹ́ni tó bá gbèjà rẹ̀ láàárọ̀ yìí.+ Tó bá jẹ́ ọlọ́run ni, ẹ jẹ́ kó gbèjà ara rẹ̀,+ torí ẹnì kan ti wó pẹpẹ rẹ̀.” 32 Torí náà, ó pe Gídíónì ní Jerubáálì* ní ọjọ́ yẹn, ó ní: “Jẹ́ kí Báálì gbèjà ara rẹ̀, torí ẹnì kan ti wó pẹpẹ rẹ̀.”
33 Gbogbo àwọn ọmọ Mídíánì,+ Ámálékì+ àti àwọn Ará Ìlà Oòrùn wá da àwọn ọmọ ogun wọn pọ̀;+ wọ́n sọdá* sí Àfonífojì* Jésírẹ́lì, wọ́n sì pàgọ́. 34 Ẹ̀mí Jèhófà wá bà lé Gídíónì,*+ ó fun ìwo,+ àwọn ọmọ Abi-ésérì+ sì kóra jọ sẹ́yìn rẹ̀. 35 Ó ránṣẹ́ káàkiri Mánásè, àwọn náà sì kóra jọ sẹ́yìn rẹ̀. Ó tún ránṣẹ́ káàkiri Áṣérì, Sébúlúnì àti Náfútálì, wọ́n sì wá pàdé rẹ̀.
36 Gídíónì wá sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Tó bá jẹ́ pé èmi lo fẹ́ lò láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀, bí o ṣe ṣèlérí+ gẹ́lẹ́, 37 mo máa tẹ́ ìṣùpọ̀ irun àgùntàn sílẹ̀ ní ibi ìpakà. Tí ìrì bá sẹ̀ sórí ìṣùpọ̀ irun náà nìkan, àmọ́ tí gbogbo ilẹ̀ tó yí i ká gbẹ, ìgbà yẹn ni màá mọ̀ pé èmi lo máa lò láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀, bí o ṣe ṣèlérí gẹ́lẹ́.” 38 Bó sì ṣe ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Nígbà tó dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, tó sì fún irun náà, omi tó fún lára irun náà kún abọ́ ńlá tí wọ́n fi ń jẹ àsè. 39 Àmọ́ Gídíónì sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ìbínú rẹ ru sí mi, àmọ́ jẹ́ kí n tún béèrè ohun kan péré. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n tún fi ìṣùpọ̀ irun náà dán ohun kan péré wò. Jọ̀ọ́ jẹ́ kí irun náà nìkan ṣoṣo gbẹ, àmọ́ kí ìrì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀.” 40 Ohun tí Ọlọ́run sì ṣe lálẹ́ ọjọ́ yẹn nìyẹn; irun yẹn nìkan ló gbẹ, àmọ́ ìrì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀.
7 Jerubáálì, ìyẹn Gídíónì+ àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá dìde ní àárọ̀ kùtù, wọ́n sì pàgọ́ síbi ìsun omi Háródù, ibùdó Mídíánì wà ní àríwá rẹ̀, níbi òkè Mórè, ní àfonífojì.* 2 Jèhófà wá sọ fún Gídíónì pé: “Àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ ti pọ̀ jù fún mi láti fi Mídíánì lé wọn lọ́wọ́.+ Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Ísírẹ́lì máa gbé ara rẹ̀ ga sí mi, wọ́n á ní, ‘Ọwọ́ ara mi ló gbà mí là.’+ 3 Jọ̀ọ́, kéde níṣojú gbogbo àwọn èèyàn náà báyìí, pé: ‘Kí ẹnikẹ́ni tó bá ń bẹ̀rù tí àyà rẹ̀ sì ń já pa dà sílé.’”+ Torí náà, Gídíónì dán wọn wò. Ìyẹn mú kí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) lára àwọn èèyàn náà pa dà sílé, ó sì ṣẹ́ ku ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000).
4 Síbẹ̀, Jèhófà sọ fún Gídíónì pé: “Àwọn èèyàn yìí ṣì pọ̀ jù. Ní kí wọ́n lọ síbi omi kí n lè bá ọ dán wọn wò níbẹ̀. Tí mo bá sọ fún ọ pé, ‘Ẹni yìí máa bá ọ lọ,’ ó máa bá ọ lọ, àmọ́ tí mo bá sọ fún ọ pé, ‘Ẹni yìí ò ní bá ọ lọ,’ kò ní bá ọ lọ.” 5 Ó wá kó àwọn èèyàn náà lọ síbi omi.
Jèhófà sì sọ fún Gídíónì pé: “Ya gbogbo àwọn tó ń fi ahọ́n lá omi bí ajá sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tó kúnlẹ̀ láti mu omi.” 6 Iye àwọn tó ń lá omi, tí wọ́n ń fi ọwọ́ bu omi sẹ́nu jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin. Àwọn yòókù kúnlẹ̀ láti mu omi.
7 Jèhófà wá sọ fún Gídíónì pé: “Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin tó lá omi ni màá fi gbà yín là, mo sì máa fi Mídíánì lé ọ lọ́wọ́.+ Jẹ́ kí gbogbo àwọn yòókù pa dà sílé.” 8 Torí náà, lẹ́yìn tí wọ́n gba oúnjẹ àtàwọn ìwo lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà, ó ní kí gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì yòókù pa dà sílé, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin náà nìkan ló sì ní kó dúró. Ibùdó Mídíánì wà nísàlẹ̀ rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀.+
9 Jèhófà sọ fún un lálẹ́ ọjọ́ yẹn pé: “Dìde, lọ gbógun ja ibùdó náà, torí mo ti fi lé ọ lọ́wọ́.+ 10 Àmọ́ tí ẹ̀rù bá ń bà ọ́ láti gbéjà kò wọ́n, kí ìwọ àti Púrà ìránṣẹ́ rẹ lọ sí ibùdó náà. 11 Tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ń sọ, lẹ́yìn náà, wàá ní ìgboyà* láti gbógun ja ibùdó náà.” Torí náà, òun àti Púrà ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí etí ibi tí àwọn ọmọ ogun náà pàgọ́ sí.
12 Mídíánì, Ámálékì àti gbogbo àwọn Ará Ìlà Oòrùn+ kóra jọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, wọ́n pọ̀ bí eéṣú, àwọn ràkúnmí wọn kò sì níye,+ wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun. 13 Gídíónì wá dé, ọkùnrin kan sì ń rọ́ àlá fún ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Àlá tí mo lá nìyí. Búrẹ́dì ribiti kan tí wọ́n fi ọkà bálì ṣe ń yí gbiri bọ̀ wá sínú ibùdó Mídíánì. Ó dé àgọ́ kan, ó sì kọ lù ú débi pé àgọ́ náà ṣubú.+ Àní, ó dojú àgọ́ náà dé, ó sì wó o lulẹ̀.” 14 Ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá sọ fún un pé: “Idà Gídíónì+ ọmọ Jóáṣì, ọkùnrin Ísírẹ́lì nìkan ló lè jẹ́. Ọlọ́run ti fi Mídíánì àti gbogbo ibùdó náà lé e lọ́wọ́.”+
15 Gbàrà tí Gídíónì gbọ́ tó rọ́ àlá náà, tó sì gbọ́ ìtumọ̀ rẹ̀,+ ó forí balẹ̀, ó sì jọ́sìn. Lẹ́yìn náà, ó pa dà sí ibùdó Ísírẹ́lì, ó sì sọ pé: “Ẹ dìde, torí Jèhófà ti fi ibùdó Mídíánì lé yín lọ́wọ́.” 16 Ó wá pín ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin náà sí àwùjọ mẹ́ta, ó fún gbogbo wọn ní ìwo+ àti ìṣà ńlá tó ṣófo, ògùṣọ̀ sì wà nínú àwọn ìṣà náà. 17 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa wò mí, ohun tí mo bá sì ṣe gẹ́lẹ́ ni kí ẹ ṣe. Tí mo bá dé etí ibùdó náà, ohun tí mo bá ṣe gẹ́lẹ́ ni kí ẹ ṣe. 18 Tí èmi àti gbogbo àwọn tó wà lọ́dọ̀ mi bá fun ìwo, kí ẹ̀yin náà fun ìwo yí ká ibùdó náà, kí ẹ sì kígbe pé, ‘Ti Jèhófà àti ti Gídíónì!’”
19 Gídíónì àti ọgọ́rùn-ún (100) ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá sí etí ibùdó ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣọ́ àárín òru,* gbàrà tí wọ́n yan àwọn ọmọ ogun tó ń ṣọ́ ibùdó sí àyè wọn. Wọ́n fun ìwo,+ wọ́n sì fọ́ àwọn ìṣà omi ńlá tó wà lọ́wọ́ wọn+ túútúú. 20 Àwùjọ ọmọ ogun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wá fun ìwo, wọ́n sì fọ́ àwọn ìṣà ńlá náà túútúú. Wọ́n fi ọwọ́ òsì di ògùṣọ̀ mú, wọ́n fun ìwo tó wà lọ́wọ́ ọ̀tún wọn, wọ́n sì kígbe pé: “Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!” 21 Ní gbogbo àkókò yẹn, kálukú wọn dúró sí àyè rẹ̀ yí ibùdó náà ká, gbogbo àwọn ọmọ ogun sì sá lọ, wọ́n ń kígbe bí wọ́n ṣe ń sá lọ.+ 22 Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin tó ń fun ìwo náà ò dáwọ́ dúró, Jèhófà sì mú kí àwọn ọmọ ogun dojú idà kọra wọn ní gbogbo ibùdó náà;+ àwọn ọmọ ogun náà sì sá lọ títí dé Bẹti-ṣítà, wọ́n sá dé Sérérà, títí dé ẹ̀yìn ìlú Ebẹli-méhólà+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Tábátì.
23 Wọ́n wá pe àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jọ láti Náfútálì, Áṣérì àti gbogbo Mánásè,+ wọ́n sì lé Mídíánì. 24 Gídíónì ránṣẹ́ sí gbogbo agbègbè olókè Éfúrémù pé: “Ẹ lọ gbógun ja Mídíánì, kí ẹ sì gba ọ̀nà tó dé ibi omi mọ́ wọn lọ́wọ́ títí dé Bẹti-bárà àti Jọ́dánì.” Gbogbo àwọn ọkùnrin Éfúrémù wá kóra jọ, wọ́n sì gba ibi omi náà títí dé Bẹti-bárà àti Jọ́dánì. 25 Wọ́n tún mú àwọn ìjòyè Mídíánì méjèèjì, ìyẹn Órébù àti Séébù; wọ́n pa Órébù lórí àpáta Órébù,+ wọ́n sì pa Séébù níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì Séébù. Wọn ò dẹ̀yìn lẹ́yìn Mídíánì,+ wọ́n sì gbé orí Órébù àti Séébù wá fún Gídíónì ní agbègbè Jọ́dánì.
8 Àwọn ọkùnrin Éfúrémù wá sọ fún un pé: “Kí lo ṣe sí wa yìí? Kí ló dé tí o ò pè wá nígbà tí o lọ bá Mídíánì jà?”+ Wọ́n sì bínú sí i gidigidi.+ 2 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ṣé ohun tí mo ṣe wá tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiyín? Ṣé èéṣẹ́ Éfúrémù + ò dáa ju ìkórè èso àjàrà Abi-ésérì lọ ni?+ 3 Ẹ̀yin ni Ọlọ́run fi àwọn ìjòyè Mídíánì, ìyẹn Órébù àti Séébù+ lé lọ́wọ́, ṣé ohun tí mo ṣe wá tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiyín?” Nígbà tó sọ̀rọ̀ báyìí,* ara wọn balẹ̀.*
4 Lẹ́yìn náà, Gídíónì dé Jọ́dánì, ó sì sọdá. Ó ti rẹ òun àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀, àmọ́ wọn ò dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn tí wọ́n ń lé. 5 Ó wá sọ fún àwọn ọkùnrin Súkótù pé: “Ẹ jọ̀ọ́ ẹ fún àwọn èèyàn tó ń tẹ̀ lé mi yìí ní ìṣù búrẹ́dì, torí ó ti rẹ̀ wọ́n, mo sì ń lé Séébà àti Sálímúnà, àwọn ọba Mídíánì.” 6 Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Súkótù sọ fún un pé: “Ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Séébà àti Sálímúnà* ni, tí a fi máa fún àwọn ọmọ ogun rẹ ní búrẹ́dì?” 7 Gídíónì wá fún wọn lésì pé: “Torí ìyẹn, tí Jèhófà bá fi Séébà àti Sálímúnà lé mi lọ́wọ́, màá fi ẹ̀gún àti òṣùṣú inú aginjù+ lù yín nílùkulù.” 8 Ó wá kúrò níbẹ̀ lọ sí Pénúélì, ó sì béèrè ohun kan náà lọ́wọ́ wọn, àmọ́ èsì tí àwọn ọkùnrin Súkótù fún un gẹ́lẹ́ ni àwọn ọkùnrin Pénúélì fún un. 9 Ló bá tún sọ fún àwọn ọkùnrin Pénúélì náà pé: “Tí mo bá pa dà ní àlàáfíà, màá wó ilé gogoro+ yìí.”
10 Séébà àti Sálímúnà wà ní Kákórì, pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun wọn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ọkùnrin. Àwọn tó ṣẹ́ kù nínú gbogbo ọmọ ogun àwọn Ará Ìlà Oòrùn+ nìyí, torí ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ọkùnrin tó ń fi idà jà ni wọ́n ti pa. 11 Gídíónì gòkè gba ọ̀nà àwọn tó ń gbé inú àgọ́ ní ìlà oòrùn Nóbà àti Jógíbéhà,+ ó sì gbógun ja ibùdó náà nígbà tí wọn ò fura. 12 Nígbà tí Séébà àti Sálímúnà sá, ó lé àwọn ọba Mídíánì méjèèjì bá, ó sì gbá wọn mú, ìyẹn Séébà àti Sálímúnà, jìnnìjìnnì sì bá gbogbo ibùdó náà.
13 Gídíónì ọmọ Jóáṣì wá gba ọ̀nà tó lọ sí Hérésì pa dà láti ojú ogun. 14 Ó mú ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Súkótù lójú ọ̀nà, ó sì béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin náà wá kọ orúkọ àwọn ìjòyè àti àwọn àgbààgbà Súkótù fún un, wọ́n jẹ́ ọkùnrin mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77). 15 Ó wá lọ bá àwọn ọkùnrin Súkótù, ó sì sọ fún wọn pé: “Séébà àti Sálímúnà tí ẹ tìtorí wọn ṣáátá mi rèé, tí ẹ sọ pé, ‘Ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Séébà àti Sálímúnà* ni, tí a fi máa fún àwọn ọmọ ogun rẹ tó ti rẹ̀ ní búrẹ́dì?’”+ 16 Ló bá mú àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì fi àwọn ẹ̀gún àti òṣùṣú inú aginjù kọ́ àwọn ọkùnrin Súkótù lọ́gbọ́n.+ 17 Ó wó ilé gogoro Pénúélì,+ ó sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà.
18 Ó bi Séébà àti Sálímúnà pé: “Irú àwọn ọkùnrin wo lẹ pa ní Tábórì?” Wọ́n fún un lésì pé: “Bí o ṣe rí ni wọ́n rí, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn rí bí ọmọ ọba.” 19 Ló bá sọ fún wọn pé: “Arákùnrin mi ni wọ́n, àwọn ọmọ ìyá mi. Bí Jèhófà ti wà, ká ní ẹ dá ẹ̀mí wọn sí ni, mi ò ní pa yín.” 20 Ó wá sọ fún Jétà àkọ́bí rẹ̀ pé: “Dìde, kí o pa wọ́n.” Àmọ́ ọ̀dọ́kùnrin náà ò fa idà rẹ̀ yọ; ẹ̀rù ń bà á, torí ó ṣì kéré. 21 Torí náà, Séébà àti Sálímúnà sọ fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ dìde, kí o sì pa wá, torí bí ẹnì kan bá ṣe lágbára tó la fi ń mọ̀ bóyá ọkùnrin ni.”* Gídíónì wá dìde, ó pa Séébà àti Sálímúnà,+ ó sì mú ohun ọ̀ṣọ́ tó rí bí òṣùpá tó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.
22 Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fún Gídíónì pé: “Máa jọba lórí wa, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ pẹ̀lú ọmọ ọmọ rẹ, torí o ti gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ Mídíánì.”+ 23 Àmọ́ Gídíónì sọ fún wọn pé: “Mi ò ní jọba lé yín lórí, ọmọ mi náà ò sì ní jọba lé yín lórí. Jèhófà ló máa jọba lé yín lórí.”+ 24 Gídíónì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹ jẹ́ kí n béèrè ohun kan lọ́wọ́ yín: kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín fún mi ní òrùka imú kan látinú ẹrù tó kó bọ̀ láti ogun.” (Wọ́n ní òrùka imú tí wọ́n fi wúrà ṣe, torí pé ọmọ Íṣímáẹ́lì+ ni wọ́n.) 25 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Ó dájú pé a máa fún ọ.” Ni wọ́n bá tẹ́ aṣọ kan, kálukú wọn sì ju òrùka imú sórí rẹ̀ látinú ẹrù tó kó bọ̀ láti ogun. 26 Ìwọ̀n òrùka imú tí wọ́n fi wúrà ṣe tó béèrè lọ́wọ́ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje (1,700) ṣékélì wúrà,* yàtọ̀ sí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tó rí bí òṣùpá, àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n máa ń so mọ́ ẹ̀gbà ọrùn, aṣọ aláwọ̀ pọ́pù tí àwọn ọba Mídíánì máa ń wọ̀ àtàwọn ẹ̀gbà ọrùn tí wọ́n yọ ní ọrùn àwọn ràkúnmí.+
27 Gídíónì wá fi ṣe éfódì+ kan, ó sì gbé e sí gbangba ní Ọ́fírà+ ìlú rẹ̀; gbogbo Ísírẹ́lì sì bá a ṣe àgbèrè ẹ̀sìn níbẹ̀,+ ó wá di ìdẹkùn fún Gídíónì àti agbo ilé rẹ̀.+
28 Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun Mídíánì+ nìyẹn, wọn ò sì yọ wọ́n lẹ́nu* mọ́; àlàáfíà wá wà ní ilẹ̀ náà* fún ogójì (40) ọdún nígbà ayé Gídíónì.+
29 Jerubáálì+ ọmọ Jóáṣì pa dà sí ilé rẹ̀, ó sì wà níbẹ̀.
30 Gídíónì bí àádọ́rin (70) ọmọkùnrin,* torí ó fẹ́ ìyàwó púpọ̀. 31 Wáhàrì* rẹ̀ tó wà ní Ṣékémù náà bí ọmọkùnrin kan fún un, ó sì sọ ọ́ ní Ábímélékì.+ 32 Gídíónì ọmọ Jóáṣì dàgbà darúgbó kó tó kú, wọ́n sì sin ín sínú ibojì Jóáṣì bàbá rẹ̀ ní Ọ́fírà ti àwọn ọmọ Abi-ésérì.+
33 Àmọ́ gbàrà tí Gídíónì kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún bá àwọn Báálì+ ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, wọ́n sì fi Baali-bérítì ṣe ọlọ́run wọn.+ 34 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò rántí Jèhófà Ọlọ́run wọn,+ ẹni tó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá tó yí wọn ká;+ 35 wọn ò sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí agbo ilé Jerubáálì, ìyẹn Gídíónì, pẹ̀lú gbogbo ohun rere tó ṣe fún Ísírẹ́lì.+
9 Nígbà tó yá, Ábímélékì+ ọmọ Jerubáálì lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ ní Ṣékémù, ó sì sọ fún àwọn àti gbogbo ìdílé bàbá rẹ̀ àgbà* pé: 2 “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ bi gbogbo àwọn olórí* ní Ṣékémù pé, ‘Èwo ló dáa jù fún yín, pé kí gbogbo àádọ́rin (70) ọmọkùnrin Jerubáálì+ máa jọba lé yín lórí àbí kí ọkùnrin kan ṣoṣo máa jọba lé yín lórí? Ẹ má gbàgbé pé ẹ̀jẹ̀ kan náà ni wá.’”*
3 Àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ wá bá a sọ ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo àwọn olórí Ṣékémù, ọkàn wọn sì fẹ́ láti tẹ̀ lé Ábímélékì, torí wọ́n sọ pé: “Ọmọ ìyá wa ni.” 4 Wọ́n wá fún un ní àádọ́rin (70) ẹyọ fàdákà látinú ilé* Baali-bérítì,+ Ábímélékì sì fi gba àwọn ọkùnrin tí kò níṣẹ́ tí wọ́n sì ya aláfojúdi, kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé e kiri. 5 Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé bàbá rẹ̀ ní Ọ́fírà,+ ó sì pa àwọn arákùnrin rẹ̀,+ àwọn ọmọ Jerubáálì, àádọ́rin (70) ọkùnrin, lórí òkúta kan. Jótámù, ọmọ Jerubáálì tó kéré jù nìkan ló ṣẹ́ kù, torí pé ó sá pa mọ́.
6 Gbogbo àwọn olórí Ṣékémù àti gbogbo Bẹti-mílò wá kóra jọ, wọ́n sì fi Ábímélékì jọba,+ nítòsí igi ńlá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó* tó wà ní Ṣékémù.
7 Nígbà tí wọ́n sọ fún Jótámù, ojú ẹsẹ̀ ló lọ dúró sórí Òkè Gérísímù,+ ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin olórí Ṣékémù kí Ọlọ́run lè fetí sí yín.
8 “Ìgbà kan wà tí àwọn igi fẹ́ lọ yan ọba tó máa jẹ lórí wọn. Wọ́n wá sọ fún igi ólífì pé, ‘Jọba lórí wa.’+ 9 Ṣùgbọ́n igi ólífì sọ fún wọn pé, ‘Ṣé kí n wá fi òróró mi sílẹ̀,* èyí tí wọ́n fi ń yin Ọlọ́run àti èèyàn, kí n sì lọ máa fì lórí àwọn igi yòókù?’ 10 Àwọn igi tún sọ fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé, ‘Wá jọba lórí wa.’ 11 Àmọ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ sọ fún wọn pé, ‘Ṣé kí n wá fi adùn mi àti èso dáadáa mi sílẹ̀, kí n sì lọ máa fì lórí àwọn igi yòókù?’ 12 Lẹ́yìn náà, àwọn igi sọ fún igi àjàrà pé, ‘Wá jọba lórí wa.’ 13 Igi àjàrà fún wọn lésì pé, ‘Ṣé kí n wá fi wáìnì tuntun mi tó ń mú kí Ọlọ́run àti èèyàn máa yọ̀ sílẹ̀, kí n sì lọ máa fì lórí àwọn igi?’ 14 Níkẹyìn, gbogbo igi yòókù sọ fún igi ẹlẹ́gùn-ún pé, ‘Wá jọba lórí wa.’+ 15 Ni igi ẹlẹ́gùn-ún bá sọ fún àwọn igi pé, ‘Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lẹ fẹ́ fi mí jọba lórí yín, ẹ wá sábẹ́ òjìji mi kí n lè dáàbò bò yín. Àmọ́ tí ẹ bá kọ̀, kí iná jáde látara igi ẹlẹ́gùn-ún kó sì jó àwọn igi kédárì Lẹ́bánónì run.’
16 “Ṣé òótọ́ inú lẹ wá fi hùwà yìí, ṣé ohun tó tọ́ lẹ sì ṣe bí ẹ ṣe fi Ábímélékì jọba,+ ṣé ìwà rere lẹ hù sí Jerubáálì àti agbo ilé rẹ̀, ṣé ohun tó sì yẹ ẹ́ lẹ ṣe fún un? 17 Nígbà tí bàbá mi jà fún yín,+ ó fi ẹ̀mí* ara rẹ wewu, kó lè gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ Mídíánì.+ 18 Àmọ́ lónìí, ẹ ti dìde sí agbo ilé bàbá mi, ẹ sì pa àwọn ọmọ rẹ̀, àádọ́rin (70) ọkùnrin, lórí òkúta kan.+ Ẹ wá fi Ábímélékì, ọmọ ẹrúbìnrin rẹ̀,+ jọba lórí àwọn olórí Ṣékémù, torí pé arákùnrin yín ni. 19 Àní, tó bá jẹ́ pé òótọ́ inú lẹ fi hùwà yìí, tó sì jẹ́ ohun tó tọ́ lẹ ṣe sí Jerubáálì àti agbo ilé rẹ̀ lónìí, ẹ jẹ́ kí inú yín máa dùn torí Ábímélékì, kí inú tiẹ̀ náà sì máa dùn torí yín. 20 Àmọ́ tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí iná jáde wá látọ̀dọ̀ Ábímélékì, kó sì jó àwọn olórí Ṣékémù àti Bẹti-mílò+ run, kí iná sì jáde wá látọ̀dọ̀ àwọn olórí Ṣékémù àti Bẹti-mílò, kó sì jó Ábímélékì run.”+
21 Jótámù+ wá sá lọ sí Bíà, ó sì ń gbé ibẹ̀ torí Ábímélékì arákùnrin rẹ̀.
22 Ọdún mẹ́ta ni Ábímélékì fi jọba* lórí Ísírẹ́lì. 23 Ọlọ́run wá jẹ́ kí Ábímélékì àti àwọn olórí Ṣékémù bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ̀yìn síra wọn,* wọ́n sì dalẹ̀ Ábímélékì. 24 Èyí á jẹ́ kí ẹ̀san ké torí ìwà ìkà tí wọ́n hù sí àádọ́rin (70) ọmọ Jerubáálì, kí Ábímélékì arákùnrin wọn sì lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn torí pé ó pa wọ́n,+ kí àwọn olórí Ṣékémù náà lè jẹ̀bi torí pé wọ́n ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀. 25 Àwọn olórí Ṣékémù wá ní kí àwọn ọkùnrin lọ lúgọ dè é lórí àwọn òkè, gbogbo ẹni tó bá gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá ni wọ́n sì máa ń jà lólè. Nígbà tó yá, Ábímélékì gbọ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀.
26 Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sọdá sí Ṣékémù,+ àwọn olórí Ṣékémù sì fọkàn tán an. 27 Wọ́n jáde lọ sóko, wọ́n sì kórè èso inú àwọn ọgbà àjàrà wọn, wọ́n tẹ̀ ẹ́, wọ́n sì ṣe àjọyọ̀, lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sínú ilé ọlọ́run wọn,+ wọ́n jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì gégùn-ún fún Ábímélékì. 28 Gáálì ọmọ Ébédì wá sọ pé: “Ta ni Ábímélékì, ta sì ni Ṣékémù tí a fi máa sìn ín? Ṣebí òun ni ọmọ Jerubáálì?+ Ṣebí Sébúlù ni kọmíṣọ́nnà rẹ̀? Ẹ máa sin àwọn ọkùnrin Hámórì, bàbá Ṣékémù! Àmọ́ kí ló dé tí a fi máa sin òun? 29 Ká ní àwọn èèyàn yìí wà lábẹ́ àṣẹ mi ni, ṣe ni ǹ bá yọ Ábímélékì nípò.” Ó wá sọ fún Ábímélékì pé: “Kó ọmọ ogun jọ sí i, kí o sì jáde wá.”
30 Nígbà tí Sébúlù ìjòyè ìlú náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Gáálì ọmọ Ébédì, inú bí i gidigidi. 31 Ó wá dọ́gbọ́n* ránṣẹ́ sí Ábímélékì pé: “Wò ó! Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ti wà ní Ṣékémù báyìí, wọ́n sì fẹ́ kẹ̀yìn àwọn ará ìlú náà sí ọ. 32 Kí ìwọ àti àwọn ọkùnrin rẹ wá ní òru, kí ẹ sì lúgọ sínú oko. 33 Gbàrà tí oòrùn bá ti yọ ní àárọ̀, kí o tètè dìde, kí o sì gbógun ja ìlú náà; tí òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ bá sì wá bá ọ jà, ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe láti ṣẹ́gun rẹ̀.”*
34 Ábímélékì àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá gbéra ní òru, wọ́n pínra sí àwùjọ mẹ́rin, wọ́n sì lúgọ láti gbógun ja Ṣékémù. 35 Nígbà tí Gáálì ọmọ Ébédì jáde lọ, tó sì dúró sí àbáwọ ẹnubodè ìlú náà, Ábímélékì àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dìde níbi tí wọ́n lúgọ sí. 36 Nígbà tí Gáálì rí àwọn èèyàn náà, ó sọ fún Sébúlù pé: “Wò ó! Àwọn èèyàn ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ látorí àwọn òkè.” Àmọ́ Sébúlù sọ fún un pé: “Òjìji àwọn òkè lò ń rí tí wọ́n dà bí èèyàn.”
37 Lẹ́yìn náà, Gáálì sọ pé: “Wò ó! Àwọn èèyàn ń bọ̀ láti àárín ilẹ̀ náà, àwùjọ ọmọ ogun kan sì ń gba ọ̀nà igi ńlá Méónẹ́nímù bọ̀.” 38 Sébúlù fún un lésì pé: “Ṣebí ò ń fọ́nnu pé, ‘Ta ni Ábímélékì tí a fi máa sìn ín?’+ Ṣebí àwọn èèyàn tí o kọ̀ nìyí? Jáde lọ báyìí, kí o lọ bá wọn jà.”
39 Gáálì wá ṣáájú àwọn olórí Ṣékémù lọ, ó sì bá Ábímélékì jà. 40 Ábímélékì lé e, Gáálì sì sá fún un, òkú wá sùn lọ bẹẹrẹbẹ títí dé ibi àbáwọ ẹnubodè ìlú náà.
41 Ábímélékì wá ń gbé ní Árúmà, Sébúlù+ sì lé Gáálì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò ní Ṣékémù. 42 Lọ́jọ́ kejì àwọn èèyàn náà jáde lọ sí oko, Ábímélékì sì gbọ́ nípa rẹ̀. 43 Ó wá kó àwọn èèyàn, ó sì pín wọn sí àwùjọ mẹ́ta, wọ́n sì lúgọ sínú oko. Nígbà tó rí àwọn èèyàn tó ń jáde látinú ìlú náà, ó gbéjà kò wọ́n, ó sì ṣá wọn balẹ̀. 44 Ábímélékì àti àwọn àwùjọ tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ bá lọ síwájú, wọ́n sì dúró síbi àbáwọ ẹnubodè ìlú ńlá náà, àmọ́ àwùjọ méjèèjì gbógun ja gbogbo àwọn tó wà nínú oko, wọ́n sì ṣá wọn balẹ̀. 45 Gbogbo ọjọ́ yẹn ni Ábímélékì fi bá ìlú náà jà, ó sì gbà á. Ó pa àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀, ó bi ìlú náà wó,+ ó sì da iyọ̀ síbẹ̀.
46 Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ilé gogoro Ṣékémù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n lọ sínú ibi ààbò* ní ilé* Eli-bérítì.+ 47 Gbàrà tí wọ́n sọ fún Ábímélékì pé gbogbo àwọn olórí ilé gogoro Ṣékémù ti kóra jọ, 48 Ábímélékì àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gun Òkè Sálímónì lọ. Ábímélékì mú àáké kan dání, ó gé ẹ̀ka igi kan, ó sì gbé e lé èjìká rẹ̀, ó wá sọ fún àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ẹ yára ṣe ohun tí ẹ rí i tí mo ṣe!” 49 Ni gbogbo àwọn èèyàn náà bá gé ẹ̀ka igi, wọ́n sì tẹ̀ lé Ábímélékì. Wọ́n wá kó àwọn ẹ̀ka igi náà ti ibi ààbò náà, wọ́n sì dáná sun ún. Bí gbogbo èèyàn ilé gogoro Ṣékémù ṣe kú nìyẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin àti obìnrin.
50 Ábímélékì wá lọ sí Tébésì; ó pàgọ́ ti Tébésì, ó sì gbà á. 51 Ilé gogoro kan tó ní ààbò wà ní àárín ìlú náà, ibẹ̀ ni gbogbo ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn olórí ìlú náà sá lọ. Wọ́n ti ara wọn mọ́ inú rẹ̀, wọ́n sì gun orí òrùlé ilé gogoro náà lọ. 52 Ábímélékì dé ilé gogoro náà, ó sì gbógun tì í. Ó sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé gogoro náà kó lè dáná sun ún. 53 Obìnrin kan wá ju ọmọ ọlọ lu Ábímélékì lórí, ó sì fọ́ agbárí rẹ̀.+ 54 Ó bá yára pe ìránṣẹ́ rẹ̀ tó gbé àwọn ohun ìjà rẹ̀, ó sọ fún un pé: “Fa idà rẹ yọ kí o sì pa mí, kí wọ́n má bàa sọ nípa mi pé, ‘Obìnrin ló pa á.’” Ìránṣẹ́ rẹ̀ wá gún un ní àgúnyọ, ó sì kú.
55 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì rí i pé Ábímélékì ti kú, gbogbo wọn pa dà sílé. 56 Bí Ọlọ́run ṣe mú ẹ̀san wá sórí Ábímélékì nìyẹn torí ìwà ibi tó hù sí bàbá rẹ̀ nígbà tó pa àwọn àádọ́rin (70) arákùnrin rẹ̀.+ 57 Ọlọ́run tún mú kí gbogbo ibi tí àwọn ọkùnrin Ṣékémù ṣe pa dà sórí wọn. Bí ègún Jótámù+ ọmọ Jerubáálì+ ṣe wá sórí wọn nìyẹn.
10 Lẹ́yìn Ábímélékì, Tólà ọmọ Púà, ọmọ Dódò, ọkùnrin kan látinú ìdílé Ísákà, dìde láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀.+ Ṣámírù ló ń gbé, ní agbègbè olókè Éfúrémù. 2 Ọdún mẹ́tàlélógún (23) ló fi jẹ́ onídàájọ́ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà, ó kú, wọ́n sì sin ín sí Ṣámírù.
3 Lẹ́yìn rẹ̀, Jáírì ọmọ Gílíádì dìde, ó sì ṣe onídàájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún méjìlélógún (22). 4 Ó ní ọgbọ̀n (30) ọmọkùnrin tó ń gun ọgbọ̀n (30) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì ní ọgbọ̀n (30) ìlú, èyí tí wọ́n ń pè ní Hafotu-jáírì+ títí di òní yìí; wọ́n wà ní ilẹ̀ Gílíádì. 5 Lẹ́yìn náà, Jáírì kú, wọ́n sì sin ín sí Kámónì.
6 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sin àwọn Báálì,+ àwọn ère Áṣítórétì, àwọn ọlọ́run Árámù,* àwọn ọlọ́run Sídónì, àwọn ọlọ́run Móábù,+ àwọn ọlọ́run àwọn ọmọ Ámónì+ àti àwọn ọlọ́run àwọn Filísínì.+ Wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, wọn ò sì sìn ín. 7 Jèhófà wá bínú gidigidi sí Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n lé àwọn Filísínì àtàwọn ọmọ Ámónì lọ́wọ́.+ 8 Wọ́n ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára, wọ́n sì fìyà jẹ wọ́n gidigidi ní ọdún yẹn. Ọdún méjìdínlógún (18) ni wọ́n fi fìyà jẹ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní òdìkejì Jọ́dánì lápá ibi tó jẹ́ ilẹ̀ àwọn Ámórì tẹ́lẹ̀ ní Gílíádì. 9 Àwọn ọmọ Ámónì náà máa ń sọdá Jọ́dánì láti lọ bá Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti ilé Éfúrémù jà; ìdààmú sì bá Ísírẹ́lì gidigidi. 10 Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,+ wọ́n sọ pé: “A ti ṣẹ̀ ọ́, torí a fi Ọlọ́run wa sílẹ̀, a sì ń sin àwọn Báálì.”+
11 Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ṣebí mo gbà yín lọ́wọ́ Íjíbítì+ àti lọ́wọ́ àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Ámónì, àwọn Filísínì,+ 12 àwọn ọmọ Sídónì, Ámálékì àti Mídíánì, nígbà tí wọ́n ń fìyà jẹ yín? Nígbà tí ẹ ké pè mí, mo gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. 13 Àmọ́ ẹ fi mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin àwọn ọlọ́run míì.+ Ìdí nìyẹn tí mi ò fi ní gbà yín sílẹ̀ mọ́.+ 14 Ẹ lọ bá àwọn ọlọ́run tí ẹ yàn, kí ẹ sì ké pè wọ́n pé kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́.+ Kí wọ́n gbà yín sílẹ̀ nígbà tí wàhálà dé bá yín.”+ 15 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ fún Jèhófà pé: “A ti ṣẹ̀. Ohunkóhun tó bá dáa lójú rẹ ni kí o ṣe sí wa. Jọ̀ọ́, ṣáà ti gbà wá sílẹ̀ lónìí.” 16 Wọ́n wá kó àwọn ọlọ́run àjèjì kúrò láàárín wọn, wọ́n sì ń sin Jèhófà,+ débi pé ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́* bí Ísírẹ́lì ṣe ń jìyà.+
17 Nígbà tó yá, a pe àwọn ọmọ Ámónì+ jọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Gílíádì. Torí náà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Mísípà. 18 Àwọn èèyàn náà àtàwọn ìjòyè Gílíádì sọ fún ara wọn pé: “Ta ló máa ṣáájú láti lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jà?+ Kó di olórí gbogbo àwọn tó ń gbé Gílíádì.”
11 Jagunjagun tó lákíkanjú ni Jẹ́fútà+ tó wá láti ìdílé Gílíádì; aṣẹ́wó ni ìyá rẹ̀, Gílíádì sì ni bàbá rẹ̀. 2 Àmọ́, ìyàwó Gílíádì náà bí àwọn ọmọkùnrin fún un. Nígbà tí àwọn ọmọ ìyàwó rẹ̀ dàgbà, wọ́n lé Jẹ́fútà jáde, wọ́n sì sọ fún un pé: “O ò ní bá wa pín ogún kankan ní agbo ilé bàbá wa, torí ọmọ obìnrin míì ni ọ́.” 3 Torí náà, Jẹ́fútà sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì lọ ń gbé ilẹ̀ Tóbù. Àwọn ọkùnrin tí kò níṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé Jẹ́fútà, wọ́n sì jọ ń rìn.
4 Nígbà tó ṣe díẹ̀, àwọn ọmọ Ámónì bá Ísírẹ́lì jà.+ 5 Nígbà tí àwọn ọmọ Ámónì bá Ísírẹ́lì jà, ojú ẹsẹ̀ làwọn àgbààgbà Gílíádì lọ mú Jẹ́fútà pa dà wá láti ilẹ̀ Tóbù. 6 Wọ́n sọ fún Jẹ́fútà pé: “Wá di ọ̀gágun wa, ká lè gbógun ja àwọn ọmọ Ámónì.” 7 Àmọ́ Jẹ́fútà sọ fún àwọn àgbààgbà Gílíádì pé: “Ṣebí ẹ̀yin lẹ kórìíra mi débi pé ẹ lé mi jáde ní ilé bàbá mi?+ Kí ló dé tí ẹ wá ń wá mi báyìí tí ìdààmú ti bá yín?” 8 Àwọn àgbààgbà Gílíádì wá sọ fún Jẹ́fútà pé: “Ìdí nìyẹn tí a fi pa dà wá bá ọ báyìí. Tí o bá tẹ̀ lé wa tí o sì bá àwọn ọmọ Ámónì jà, wàá di olórí wa àti gbogbo àwọn tó ń gbé ní Gílíádì.”+ 9 Torí náà, Jẹ́fútà sọ fún àwọn àgbààgbà Gílíádì pé: “Tí ẹ bá mú mi pa dà láti bá àwọn ọmọ Ámónì jà, tí Jèhófà sì bá mi ṣẹ́gun wọn, ó dájú pé màá di olórí yín!” 10 Àwọn àgbààgbà Gílíádì sọ fún Jẹ́fútà pé: “Kí Jèhófà jẹ́ ẹlẹ́rìí* láàárín wa tí a ò bá ṣe ohun tí o sọ.” 11 Jẹ́fútà wá tẹ̀ lé àwọn àgbààgbà Gílíádì lọ, àwọn èèyàn náà sì sọ ọ́ di olórí àti ọ̀gágun wọn. Jẹ́fútà sì tún gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ níwájú Jèhófà ní Mísípà.+
12 Jẹ́fútà wá ránṣẹ́ sí ọba àwọn ọmọ Ámónì+ pé: “Kí ni mo fi ṣe ọ́* tí o fi wá gbógun ja ilẹ̀ mi?” 13 Ọba àwọn ọmọ Ámónì sọ fún àwọn tí Jẹ́fútà rán wá pé: “Torí pé nígbà tí Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì,+ wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Áánónì+ dé Jábókù títí dé Jọ́dánì.+ Ó yá, dá a pa dà ní àlàáfíà.” 14 Àmọ́ Jẹ́fútà ní kí àwọn ìránṣẹ́ náà pa dà sọ́dọ̀ ọba àwọn ọmọ Ámónì, 15 kí wọ́n sì sọ fún un pé:
“Ohun tí Jẹ́fútà sọ nìyí: ‘Ísírẹ́lì ò gba ilẹ̀ àwọn ọmọ Móábù+ àti ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ 16 torí nígbà tí Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, wọ́n rin aginjù títí dé Òkun Pupa,+ wọ́n sì dé Kádéṣì.+ 17 Ísírẹ́lì wá ránṣẹ́ sí ọba Édómù+ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ ká gba ilẹ̀ rẹ kọjá,” àmọ́ ọba Édómù ò gbà. Wọ́n tún ránṣẹ́ sí ọba Móábù,+ àmọ́ kò gbà. Ísírẹ́lì ò wá kúrò ní Kádéṣì.+ 18 Nígbà tí wọ́n rin aginjù, wọn ò gba inú ilẹ̀ Édómù+ àti ilẹ̀ Móábù kọjá. Apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Móábù+ ni wọ́n gbà, wọ́n sì pàgọ́ sí agbègbè Áánónì; wọn ò wọnú ààlà Móábù,+ torí Áánónì ni ààlà Móábù.
19 “‘Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì ránṣẹ́ sí Síhónì ọba àwọn Ámórì, ọba Hẹ́ṣíbónì, Ísírẹ́lì sì sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ ká gba ilẹ̀ rẹ kọjá sí àyè wa.”+ 20 Àmọ́ Síhónì kò fọkàn tán Ísírẹ́lì, kò gbà kí wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá, torí náà, Síhónì kó gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ jọ, wọ́n pàgọ́ sí Jáhásì, wọ́n sì bá Ísírẹ́lì jà.+ 21 Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wá fi Síhónì àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, torí náà wọ́n ṣẹ́gun wọn, Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn Ámórì tó ń gbé ilẹ̀ náà.+ 22 Bí wọ́n ṣe gba gbogbo ilẹ̀ àwọn Ámórì nìyẹn, láti Áánónì dé Jábókù àti láti aginjù títí dé Jọ́dánì.+
23 “‘Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ló lé àwọn Ámórì kúrò níwájú Ísírẹ́lì èèyàn rẹ̀,+ ṣé o wá fẹ́ lé wọn kúrò ni? 24 Ṣebí ohunkóhun tí Kémóṣì+ ọlọ́run rẹ bá fún ọ pé kí o gbà lo máa ń gbà? Torí náà gbogbo àwọn tí Jèhófà Ọlọ́run wa bá lé kúrò níwájú wa la máa lé kúrò.+ 25 Ṣé ìwọ wá sàn ju Bálákì+ ọmọ Sípórì, ọba Móábù lọ ni? Ṣé ó bá Ísírẹ́lì fa ohunkóhun rí, àbí ó bá wọn jà rí? 26 Nígbà tí Ísírẹ́lì ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì àti àwọn àrọko rẹ̀* àti Áróérì àti àwọn àrọko rẹ̀+ àti ní gbogbo ìlú tó wà létí Áánónì fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọdún, kí ló dé tí ẹ ò gbìyànjú rárá láti gbà wọ́n pa dà nígbà yẹn?+ 27 Mi ò ṣẹ̀ ọ́ rárá, ìwọ lo ṣe ohun tí kò dáa bí o ṣe wá gbógun jà mí. Kí Jèhófà Onídàájọ́+ ṣe ìdájọ́ lónìí láàárín àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti àwọn èèyàn Ámónì.’”
28 Àmọ́ ọba àwọn ọmọ Ámónì kò fetí sí ohun tí Jẹ́fútà ní kí wọ́n sọ fún un.
29 Ẹ̀mí Jèhófà wá bà lé Jẹ́fútà,+ ó sì gba Gílíádì àti Mánásè kọjá lọ sí Mísípè ti Gílíádì,+ láti Mísípè ti Gílíádì ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì.
30 Jẹ́fútà wá jẹ́ ẹ̀jẹ́+ kan fún Jèhófà, ó ní: “Tí o bá fi àwọn ọmọ Ámónì lé mi lọ́wọ́, 31 tí mo bá pa dà ní àlàáfíà látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, ẹnikẹ́ni tó bá jáde ní ẹnu ọ̀nà ilé mi wá pàdé mi máa di ti Jèhófà,+ màá sì fi onítọ̀hún rú ẹbọ sísun.”+
32 Lẹ́yìn náà, Jẹ́fútà lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jà, Jèhófà sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́. 33 Ó pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ láti Áróérì títí dé Mínítì, ogún (20) ìlú, títí lọ dé Ebẹli-kérámímù. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì nìyẹn.
34 Níkẹyìn, Jẹ́fútà dé sí ilé rẹ̀ ní Mísípà,+ wò ó! ọmọbìnrin rẹ̀ ló ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀, ó ń lu ìlù tanboríìnì, ó sì ń jó! Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tó bí. Kò ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin míì. 35 Nígbà tó rí i, ó fa aṣọ ara rẹ̀ ya, ó sì sọ pé: “Áà, ọmọbìnrin mi! O ti mú kí ọkàn mi bà jẹ́,* torí ìwọ ni ẹni tí màá ní kó lọ. Mo ti la ẹnu mi sí Jèhófà, mi ò sì lè yí i pa dà.”+
36 Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Bàbá mi, tí o bá ti la ẹnu rẹ sí Jèhófà, ohun tí o ṣèlérí+ ni kí o ṣe sí mi, Jèhófà kúkú ti bá ọ gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ọmọ Ámónì.” 37 Ó wá sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Ohun tí o máa ṣe fún mi nìyí: Jẹ́ kí n dá wà fún oṣù méjì, sì jẹ́ kí n lọ síbi àwọn òkè, kí èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi obìnrin sì sunkún torí pé mo jẹ́ wúńdíá.”*
38 Ó wá sọ fún un pé: “Máa lọ!” Torí náà, ó ní kó lọ fún oṣù méjì, òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì lọ síbi àwọn òkè láti lọ sunkún torí ó jẹ́ wúńdíá. 39 Lẹ́yìn oṣù méjì, ó pa dà sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀, ó sì ṣe ohun tó jẹ́jẹ̀ẹ́ nípa rẹ̀.+ Ọmọbìnrin náà ò bá ọkùnrin lò pọ̀ rárá. Torí náà, ó di àṣà* wọn ní Ísírẹ́lì pé: 40 Lọ́dọọdún, àwọn ọ̀dọ́bìnrin ní Ísírẹ́lì máa ń lọ yin ọmọbìnrin Jẹ́fútà ọmọ Gílíádì ní ọjọ́ mẹ́rin lọ́dún.
12 Wọ́n ránṣẹ́ pe àwọn ọkùnrin Éfúrémù, wọ́n sì sọdá sí Sáfónì,* wọ́n wá sọ fún Jẹ́fútà pé: “Kí ló dé tí o ò pè wá pé ká bá ọ lọ nígbà tí o sọdá lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jà?+ A máa dáná sun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.” 2 Àmọ́ Jẹ́fútà sọ fún wọn pé: “Èmi àtàwọn èèyàn mi bá àwọn ọmọ Ámónì jà gidigidi. Mo pè yín pé kí ẹ wá ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ ẹ ò gbà mí lọ́wọ́ wọn. 3 Nígbà tí mo rí i pé ẹ ò wá gbà mí sílẹ̀, mo pinnu pé màá fi ẹ̀mí ara mi wewu,* mo lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jà,+ Jèhófà sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́. Kí ló wá dé tí ẹ fi wá bá mi jà lónìí?”
4 Ni Jẹ́fútà bá kó gbogbo àwọn ọkùnrin Gílíádì+ jọ, wọ́n sì bá Éfúrémù jà; àwọn ọkùnrin Gílíádì ṣẹ́gun àwọn Éfúrémù tí wọ́n sọ pé: “Ìsáǹsá lásánlàsàn láti Éfúrémù ni yín, ẹ̀yin ọmọ Gílíádì tí ẹ wà láàárín Éfúrémù àti Mánásè.” 5 Gílíádì wá gba ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò Jọ́dánì+ mọ́ Éfúrémù lọ́wọ́; nígbà tí àwọn ọkùnrin Éfúrémù sì ń wá bí wọ́n á ṣe sá lọ, wọ́n á sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí n sọdá”; àwọn ọkùnrin Gílíádì á wá bi wọ́n níkọ̀ọ̀kan pé: “Ṣé ọmọ Éfúrémù ni ọ́?” Tó bá fèsì pé, “Rárá!” 6 wọ́n á ní: “Jọ̀ọ́ sọ pé Ṣíbólẹ́tì.” Àmọ́ ó máa sọ pé: “Síbólẹ́tì,” torí kò lè pe ọ̀rọ̀ yẹn dáadáa. Wọ́n á wá mú un, wọ́n á sì pa á níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú Jọ́dánì. Bí wọ́n ṣe pa ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbẹ̀rún méjì (42,000) àwọn Éfúrémù nígbà yẹn nìyẹn.
7 Ọdún mẹ́fà ni Jẹ́fútà fi jẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà, Jẹ́fútà ọmọ Gílíádì kú, wọ́n sì sin ín sí ìlú rẹ̀ ní Gílíádì.
8 Íbísánì láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù di onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì lẹ́yìn rẹ̀.+ 9 Ó ní ọgbọ̀n (30) ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n (30) ọmọbìnrin. Ó ní kí àwọn ọmọbìnrin òun lọ fẹ́ àwọn ọkùnrin tí kì í ṣe ara agbo ilé òun, ó sì mú ọgbọ̀n (30) obìnrin wá pé kí wọ́n di ìyàwó àwọn ọmọkùnrin òun. Ọdún méje ló fi jẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. 10 Lẹ́yìn náà, Íbísánì kú, wọ́n sì sin ín sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
11 Lẹ́yìn rẹ̀, Élónì ọmọ Sébúlúnì di onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì; ọdún mẹ́wàá ló fi jẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. 12 Élónì ọmọ Sébúlúnì kú, wọ́n sì sin ín sí Áíjálónì ní ilẹ̀ Sébúlúnì.
13 Lẹ́yìn rẹ̀, Ábídónì ọmọ Hílẹ́lì ará Pírátónì di onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. 14 Ó ní ogójì (40) ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n (30) ọmọ ọmọ tí wọ́n ń gun àádọ́rin (70) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ọdún mẹ́jọ ló fi jẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. 15 Ábídónì ọmọ Hílẹ́lì ará Pírátónì kú, wọ́n sì sin ín sí Pírátónì ní ilẹ̀ Éfúrémù ní òkè ọmọ Ámálékì.+
13 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ Jèhófà sì fi wọ́n lé àwọn Filísínì+ lọ́wọ́ fún ogójì (40) ọdún.
2 Láàárín àkókò yìí, ọkùnrin ará Sórà+ kan wà, ó wá látinú ìdílé àwọn ọmọ Dánì,+ Mánóà+ ni orúkọ rẹ̀. Ìyàwó rẹ̀ yàgàn, kò sì bímọ kankan.+ 3 Nígbà tó yá, áńgẹ́lì Jèhófà fara han obìnrin náà, ó sì sọ fún un pé: “Wò ó, àgàn ni ọ́, o ò bímọ. Àmọ́ o máa lóyún, o sì máa bí ọmọkùnrin kan.+ 4 Rí i pé o ò mu wáìnì tàbí ohunkóhun tó ní ọtí,+ má sì jẹ ohun àìmọ́ kankan.+ 5 Wò ó! O máa lóyún, o sì máa bí ọmọkùnrin kan, abẹ kankan ò gbọ́dọ̀ kàn án lórí,+ torí Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà máa jẹ́ látìgbà tí o bá ti bí i,* òun ló sì máa ṣáájú láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Filísínì.”+
6 Obìnrin náà wá lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ kan wá sọ́dọ̀ mi, ó rí bí áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́, ó ń bani lẹ́rù gidigidi. Mi ò béèrè ibi tó ti wá lọ́wọ́ rẹ̀, kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi.+ 7 Àmọ́ ó sọ fún mi pé, ‘Wò ó! O máa lóyún, o sì máa bí ọmọkùnrin kan. Má mu wáìnì tàbí ohunkóhun tó ní ọtí, má sì jẹ ohun àìmọ́ kankan, torí Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà máa jẹ́ látìgbà tí o bá ti bí i* títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’”
8 Mánóà bẹ Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, Jèhófà. Jẹ́ kí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ rán wá tún pa dà wá, kó sọ fún wa ohun tí a máa ṣe nípa ọmọ tí a máa bí.” 9 Ọlọ́run tòótọ́ wá fetí sí Mánóà, áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́ sì pa dà wá bá obìnrin náà nígbà tó jókòó sínú oko; Mánóà ọkọ rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Obìnrin náà yára sáré lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Wò ó! Ọkùnrin tó wá bá mi lọ́jọ́sí tún fara hàn mí.”+
11 Mánóà dìde, ó sì tẹ̀ lé ìyàwó rẹ̀. Ó wá bá ọkùnrin náà, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ ni ọkùnrin tó bá ìyàwó mi sọ̀rọ̀?” Ó fèsì pé: “Èmi ni.” 12 Mánóà bá sọ pé: “Kó rí bí o ṣe sọ! Báwo ni ìgbésí ayé ọmọ náà ṣe máa rí, iṣẹ́ wo ló sì máa ṣe?”+ 13 Áńgẹ́lì Jèhófà dá Mánóà lóhùn pé: “Kí ìyàwó rẹ yẹra fún gbogbo ohun tí mo sọ fún un.+ 14 Kó má jẹ ohunkóhun tó wá látara èso àjàrà, kó má mu wáìnì tàbí ohunkóhun tó ní ọtí,+ kó má sì jẹ ohun àìmọ́ kankan.+ Kó máa tẹ̀ lé gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un.”
15 Mánóà sọ fún áńgẹ́lì Jèhófà pé: “Jọ̀ọ́, dúró, jẹ́ ká se ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọ.”+ 16 Àmọ́ áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Mánóà pé: “Tí mo bá dúró, mi ò ní jẹ oúnjẹ rẹ; àmọ́ tó bá wù ọ́ láti rú ẹbọ sísun sí Jèhófà, o lè rú u.” Mánóà ò mọ̀ pé áńgẹ́lì Jèhófà ni. 17 Mánóà wá sọ fún áńgẹ́lì Jèhófà pé: “Kí ni orúkọ rẹ,+ ká lè bọlá fún ọ tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?” 18 Àmọ́ áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi ń béèrè orúkọ mi, nígbà tí o rí i pé àgbàyanu ni?”
19 Mánóà wá mú ọmọ ewúrẹ́ náà àti ọrẹ ọkà, ó sì fi wọ́n rúbọ lórí àpáta sí Jèhófà. Ọkùnrin náà ń ṣe ohun ìyanu kan, bí Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ ṣe ń wò ó. 20 Bí ọwọ́ iná náà ṣe ń ròkè lọ sí ọ̀run látorí pẹpẹ, áńgẹ́lì Jèhófà gba inú ọwọ́ iná tó ń jó látorí pẹpẹ náà lọ sókè bí Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ ṣe ń wò ó. Wọ́n sì dojú bolẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 21 Áńgẹ́lì Jèhófà ò sì fara han Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ mọ́. Ìgbà yẹn ni Mánóà wá mọ̀ pé áńgẹ́lì Jèhófà ni.+ 22 Mánóà wá sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Ó dájú pé a máa kú, torí Ọlọ́run ni a rí.”+ 23 Àmọ́ ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Tó bá jẹ́ pé Jèhófà fẹ́ pa wá ni, kò ní gba ẹbọ sísun+ àti ọrẹ ọkà lọ́wọ́ wa, kò ní fi gbogbo nǹkan yìí hàn wá, kò sì ní sọ ìkankan nínú nǹkan wọ̀nyí fún wa.”
24 Lẹ́yìn náà, obìnrin náà bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Sámúsìn;+ bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà, Jèhófà ń bù kún un. 25 Nígbà tó yá, ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í darí rẹ̀+ ní Mahane-dánì,+ láàárín Sórà àti Éṣítáólì.+
14 Sámúsìn sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Tímúnà, ó sì rí obìnrin Filísínì* kan ní Tímúnà. 2 Ó wá lọ sọ fún bàbá àti ìyá rẹ̀ pé: “Mo rí obìnrin Filísínì kan ní Tímúnà, mo sì fẹ́ kí ẹ fẹ́ ẹ fún mi kí n fi ṣe aya.” 3 Àmọ́, bàbá àti ìyá rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣé o ò rí obìnrin kankan láàárín àwọn mòlẹ́bí rẹ àti gbogbo àwọn èèyàn wa ni?+ Ṣé àárín àwọn Filísínì aláìdádọ̀dọ́* ló yẹ kí o ti lọ fẹ́ ìyàwó?” Àmọ́ Sámúsìn sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Òun ni kí o fẹ́ fún mi, torí òun lẹni tó yẹ mí.”* 4 Bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ ò mọ̀ pé Jèhófà ló fẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀, torí Ó ti ń ro bó ṣe máa gbógun ja àwọn Filísínì, torí pé àwọn Filísínì ń jọba lé Ísírẹ́lì lórí nígbà yẹn.+
5 Sámúsìn pẹ̀lú bàbá àti ìyá rẹ̀ wá sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Tímúnà. Nígbà tó dé àwọn ọgbà àjàrà Tímúnà, wò ó! kìnnìún* kan ń ké ramúramù bọ̀ wá bá a. 6 Àmọ́ ẹ̀mí Jèhófà fún un lágbára,+ ó sì fà á ya sí méjì, bí èèyàn ṣe ń fi ọwọ́ lásán fa ọmọ ewúrẹ́ ya sí méjì. Àmọ́ kò sọ ohun tó ṣe fún bàbá àti ìyá rẹ̀. 7 Ó wá lọ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, òun ló ṣì tọ́ lójú Sámúsìn.+
8 Lẹ́yìn náà, nígbà tó ń pa dà lọ kó lè mú obìnrin náà wá sílé,+ ó yà wo òkú kìnnìún náà, ó sì rí oyin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòkòrò oyin nínú òkú kìnnìún náà. 9 Ó wá fá oyin náà sọ́wọ́, ó sì ń lá a bó ṣe ń rìn lọ. Nígbà tó pa dà lọ bá bàbá àti ìyá rẹ̀, ó fún wọn jẹ lára rẹ̀. Àmọ́ kò sọ fún wọn pé inú òkú kìnnìún ni òun ti fá oyin náà.
10 Bàbá rẹ̀ lọ bá obìnrin náà, Sámúsìn sì se àsè ńlá kan níbẹ̀, torí bí àwọn ọ̀dọ́kùnrin ṣe máa ń ṣe nìyẹn. 11 Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n mú àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n (30) wá, tí wọ́n máa wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 12 Sámúsìn wá sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún yín. Tí ẹ bá já a tí ẹ sì sọ ìdáhùn rẹ̀ fún mi láàárín ọjọ́ méje tí a máa fi jẹ àsè yìí, màá fún yín ní ọgbọ̀n (30) aṣọ ọ̀gbọ̀* àti ọgbọ̀n (30) ẹ̀wù. 13 Àmọ́ tí ẹ ò bá lè sọ ìdáhùn rẹ̀ fún mi, ẹ máa fún mi ní ọgbọ̀n (30) aṣọ ọ̀gbọ̀ àti ọgbọ̀n (30) ẹ̀wù.” Wọ́n sọ fún un pé: “Pa àlọ́ rẹ fún wa; a fẹ́ gbọ́.” 14 Ó wá sọ fún wọn pé:
“Látinú ohun tó ń jẹ nǹkan ni oúnjẹ ti wá,
Látinú alágbára sì ni ohun tó dùn ti wá.”+
Wọn ò rí àlọ́ náà já fún ọjọ́ mẹ́ta. 15 Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n sọ fún ìyàwó Sámúsìn pé: “Tan ọkọ rẹ+ kó lè sọ ìdáhùn àlọ́ náà fún wa. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a máa dáná sun ìwọ àti ilé bàbá rẹ. Ṣé torí àtigba ohun ìní wa lẹ ṣe pè wá síbí ni?” 16 Ìyàwó Sámúsìn bá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún sí i lọ́rùn, ó sì sọ pé: “Ó dájú pé o kórìíra mi; o ò nífẹ̀ẹ́ mi.+ O pa àlọ́ kan fún àwọn èèyàn mi, àmọ́ o ò sọ ìdáhùn rẹ̀ fún mi.” Ló bá sọ fún un pé: “Mi ò sọ fún bàbá àti ìyá mi pàápàá! Ṣé ó wá yẹ kí n sọ ọ́ fún ọ?” 17 Síbẹ̀ kò yéé sunkún sí i lọ́rùn fún ọjọ́ tó kù nínú àsè ọlọ́jọ́ méje náà. Níkẹyìn, ó sọ ọ́ fún un ní ọjọ́ keje, torí pé ó ti fòòró ẹ̀mí rẹ̀. Obìnrin náà sì lọ já àlọ́+ náà fún àwọn èèyàn rẹ̀. 18 Torí náà, kí oòrùn tó wọ̀* ní ọjọ́ keje, àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé:
“Kí ló dùn ju oyin lọ,
Kí ló sì lágbára ju kìnnìún lọ?”+
Ó fún wọn lésì pé:
“Ká ní ẹ ò fi ọmọ màlúù mi túlẹ̀ ni,+
Ẹ ò bá má lè rí ìdáhùn sí àlọ́ mi.”
19 Ẹ̀mí Jèhófà wá fún un lágbára,+ ó sì lọ sí Áṣíkẹ́lónì,+ ó ṣá ọgbọ̀n (30) nínú àwọn ọkùnrin wọn balẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ wọn, ó wá kó àwọn aṣọ náà fún àwọn tó já àlọ́ náà.+ Inú ń bí i gidigidi bó ṣe ń gòkè pa dà lọ sí ilé bàbá rẹ̀.
20 Wọ́n wá fi ìyàwó Sámúsìn+ fún ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.+
15 Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, nígbà ìkórè àlìkámà,* Sámúsìn lọ wo ìyàwó rẹ̀, ó mú ọmọ ewúrẹ́ kan dání. Ó sọ pé: “Ó wù mí kí n lọ bá ìyàwó mi nínú yàrá.”* Àmọ́ bàbá obìnrin náà ò jẹ́ kó wọlé. 2 Bàbá obìnrin náà sọ pé: “Èrò mi ni pé, ‘Ó dájú pé o kórìíra rẹ̀.’+ Torí náà, mo fún ọ̀rẹ́ ìwọ ọkọ ìyàwó.+ Ṣebí àbúrò rẹ̀ rẹwà jù ú lọ? Jọ̀ọ́, mú un dípò rẹ̀.” 3 Àmọ́ Sámúsìn sọ fún wọn pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, àwọn Filísínì ò lè dá mi lẹ́bi pé mo ṣe wọ́n léṣe.”
4 Torí náà, Sámúsìn lọ mú ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀. Ó wá mú àwọn ògùṣọ̀, ó so ìrù àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà mọ́ra, ó sì fi ògùṣọ̀ kan sáàárín ìrù méjì. 5 Ó wá fi iná sí àwọn ògùṣọ̀ náà, ó sì rán àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà lọ sínú oko ọkà àwọn Filísínì. Gbogbo ohun tó wà níbẹ̀ ló dáná sun, látorí ìtí ọkà dórí ọkà tó wà ní òró, títí kan àwọn ọgbà àjàrà àti àwọn igi ólífì.
6 Àwọn Filísínì béèrè pé: “Ta ló ṣe èyí?” Wọ́n sọ fún wọn pé: “Sámúsìn ọkọ ọmọ ará Tímúnà ni, torí pé ọkùnrin náà gba ìyàwó rẹ̀, ó sì fún ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó.”+ Ni àwọn Filísínì bá lọ dáná sun obìnrin náà àti bàbá rẹ̀.+ 7 Sámúsìn wá sọ fún wọn pé: “Tó bá jẹ́ pé bí ẹ ṣe ń ṣe nìyí, mi ò ní jáwọ́ títí màá fi gbẹ̀san lára yín.”+ 8 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n níkọ̀ọ̀kan,* ó pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ, lẹ́yìn náà, ó lọ ń gbé inú ihò* kan ní àpáta Étámì.
9 Lẹ́yìn náà, àwọn Filísínì wá pàgọ́ sí Júdà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn káàkiri Léhì.+ 10 Àwọn ọkùnrin Júdà wá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ wá gbógun tì wá?” Wọ́n fèsì pé: “A wá mú* Sámúsìn ni, ká lè ṣe ohun tó ṣe fún wa sí òun náà.” 11 Torí náà, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin Júdà wá lọ síbi ihò* àpáta Étámì, wọ́n sì sọ fún Sámúsìn pé: “Ṣé o ò mọ̀ pé àwọn Filísínì ló ń jọba lórí wa ni?+ Kí ló dé tí o ṣe báyìí sí wa?” Ó sọ fún wọn pé: “Ohun tí wọ́n ṣe sí mi ni mo ṣe sí wọn.” 12 Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé: “A wá mú* ọ ká lè fi ọ́ lé àwọn Filísínì lọ́wọ́ ni.” Sámúsìn wá sọ pé: “Ẹ búra fún mi pé ẹ̀yin fúnra yín ò ní ṣèkà fún mi.” 13 Wọ́n sọ fún un pé: “Rárá, a kàn máa dè ọ́ ni, a sì máa fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, àmọ́ a ò ní pa ọ́.”
Wọ́n wá fi okùn tuntun méjì dè é, wọ́n sì gbé e jáde nínú àpáta náà. 14 Nígbà tó dé Léhì, àwọn Filísínì kígbe ayọ̀ bí wọ́n ṣe rí i. Nígbà náà, ẹ̀mí Jèhófà fún un lágbára,+ àwọn okùn tí wọ́n fi de ọwọ́ rẹ̀ wá dà bíi fọ́nrán òwú ọ̀gbọ̀ tí iná jó gbẹ, àwọn ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ sì yọ́.+ 15 Ó rí egungun tútù kan tó jẹ́ egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; ó na ọwọ́ mú un, ó sì fi ṣá ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin balẹ̀.+ 16 Sámúsìn wá sọ pé:
“Pẹ̀lú egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, òkìtì kan, òkìtì méjì!
Mo fi egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ṣá ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin balẹ̀.”+
17 Nígbà tó sọ̀rọ̀ tán, ó sọ egungun náà nù, ó sì pe ibẹ̀ ní Ramati-léhì.*+ 18 Òùngbẹ wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ ẹ́ gan-an, ló bá ké pe Jèhófà, ó sì sọ pé: “Ìwọ lo jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ ṣẹ́gun lọ́nà tó kàmàmà, àmọ́ ṣé kí òùngbẹ wá pa mí ni, kí ọwọ́ àwọn aláìdádọ̀dọ́* sì tẹ̀ mí?” 19 Ọlọ́run wá mú kí kòtò kan tó wà ní Léhì lanu, omi sì ṣàn jáde látinú rẹ̀.+ Nígbà tó mumi, okun* rẹ̀ pa dà, ó sì sọ jí. Ìdí nìyẹn tó fi pe ibẹ̀ ní Ẹn-hákórè,* èyí tó wà ní Léhì títí dòní.
20 Ogún (20) ọdún+ ló fi jẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì nígbà ayé àwọn Filísínì.
16 Nígbà kan, Sámúsìn lọ sí Gásà, ó rí obìnrin aṣẹ́wó kan níbẹ̀, ó sì wọlé lọ bá a. 2 Wọ́n sọ fún àwọn ará Gásà pé: “Sámúsìn ti wá síbí.” Torí náà, wọ́n yí i ká, wọ́n sì lúgọ dè é sí ẹnubodè ìlú náà ní òru mọ́jú. Wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ síbẹ̀ ní gbogbo òru náà, wọ́n ń sọ fún ara wọn pé: “Tí ilẹ̀ bá mọ́, a máa pa á.”
3 Àmọ́ Sámúsìn dùbúlẹ̀ síbẹ̀ títí di ọ̀gànjọ́ òru. Ó wá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, ó mú àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè ìlú náà àti àwọn òpó ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjèèjì, ó sì fà wọ́n tu pẹ̀lú ọ̀pá ìdábùú rẹ̀. Ó gbé wọn sí èjìká rẹ̀, ó sì gbé wọn lọ sórí òkè tó dojú kọ Hébúrónì.
4 Lẹ́yìn náà, ó nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dẹ̀lílà+ ní Àfonífojì Sórékì. 5 Àwọn alákòóso Filísínì wá lọ bá obìnrin náà, wọ́n sì sọ pé: “Tàn án,*+ kí o lè mọ ohun tó mú kó lágbára tó báyìí àti bí a ṣe lè kápá rẹ̀, ká dè é, ká sì borí rẹ̀. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa fún ọ ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún (1,100) ẹyọ fàdákà.”
6 Lẹ́yìn náà, Dẹ̀lílà sọ fún Sámúsìn pé: “Jọ̀ọ́, sọ fún mi ibi tí o ti rí agbára tó pọ̀ tó báyìí àti ohun tí èèyàn lè fi dè ọ́, kó sì borí rẹ.” 7 Sámúsìn sọ fún un pé: “Tí wọ́n bá fi okùn tútù méje tí wọ́n ń so mọ́ ọrun* dè mí, mi ò ní lágbára mọ́, mi ò sì ní yàtọ̀ sí àwọn ọkùnrin yòókù.” 8 Àwọn alákòóso Filísínì wá mú okùn tútù méje tí wọ́n ń so mọ́ ọrun wá fún obìnrin náà, ó sì fi dè é. 9 Wọ́n wá lọ lúgọ sí yàrá inú, ó sì ké jáde pé: “Sámúsìn, àwọn Filísínì ti wá mú ọ!” Ló bá já àwọn okùn náà, bí òwú ọ̀gbọ̀* ṣe máa ń tètè já tí iná bá kàn án.+ Wọn ò mọ àṣírí agbára rẹ̀.
10 Dẹ̀lílà wá sọ fún Sámúsìn pé: “Wò ó! O ti tàn mí,* o sì ti parọ́ fún mi. Jọ̀ọ́, sọ ohun tí èèyàn lè fi dè ọ́ fún mi.” 11 Ló bá sọ fún obìnrin náà pé: “Tí wọ́n bá fi okùn tuntun tí wọn ò tíì fi ṣiṣẹ́ rí dè mí, mi ò ní lágbára mọ́, mi ò sì ní yàtọ̀ sí àwọn ọkùnrin yòókù.” 12 Dẹ̀lílà wá mú àwọn okùn tuntun, ó fi dè é, ó sì ké jáde pé: “Sámúsìn, àwọn Filísínì ti wá mú ọ!” (Ní gbogbo ìgbà yẹn, àwọn kan ti lúgọ sí yàrá inú.) Ló bá já àwọn okùn náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀ bí òwú.+
13 Lẹ́yìn náà, Dẹ̀lílà sọ fún Sámúsìn pé: “O ṣì ń tàn mí títí di báyìí, o sì ń parọ́ fún mi.+ Sọ ohun tí èèyàn lè fi dè ọ́ fún mi.” Ló bá sọ fún obìnrin náà pé: “Tí o bá fi òwú tí wọ́n fi ń hun aṣọ di ìdì-irun méje orí mi.” 14 Ó wá fi igi tí wọ́n fi ń hun aṣọ dè é pinpin, ó sì ké jáde pé: “Sámúsìn, àwọn Filísínì ti wá mú ọ!” Ló bá jí lójú oorun, ó sì fa igi tí wọ́n fi ń hun aṣọ àti òwú náà yọ.
15 Obìnrin náà wá sọ fún un pé: “Báwo lo ṣe máa sọ pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ,’+ nígbà tí ọkàn rẹ ò sí lọ́dọ̀ mi? Ẹ̀ẹ̀mẹta lo ti tàn mí báyìí, o ò sì tíì sọ ibi tí o ti rí agbára ńlá rẹ fún mi.”+ 16 Torí pé ojoojúmọ́ ló ń yọ ọ́ lẹ́nu tó sì ń fòòró ẹ̀mí rẹ̀, ó rẹ̀ ẹ́* débi pé ẹ̀mí rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́.+ 17 Níkẹyìn, ó sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún un, ó ní: “Abẹ kò kan orí mi rí, torí Násírì Ọlọ́run ni mí látìgbà tí wọ́n ti bí mi.*+ Tí mo bá gé irun mi, agbára mi máa lọ, mi ò ní lókun mọ́, mi ò sì ní yàtọ̀ sí gbogbo ọkùnrin yòókù.”
18 Nígbà tí Dẹ̀lílà rí i pé ó ti sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún òun, ó ránṣẹ́ pe àwọn alákòóso Filísínì+ lójú ẹsẹ̀, ó ní: “Lọ́tẹ̀ yìí, ẹ máa bọ̀, torí ó ti sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún mi.” Torí náà, àwọn alákòóso Filísínì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì mú owó náà dání. 19 Obìnrin náà mú kí Sámúsìn sùn lọ sórí orúnkún rẹ̀; ó wá pe ọkùnrin kan pé kó gé ìdì-irun méje orí rẹ̀. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kápá rẹ̀ nìyẹn, torí agbára rẹ̀ ti ń lọ. 20 Ó wá ké jáde pé: “Sámúsìn, àwọn Filísínì ti wá mú ọ!” Ó jí lójú oorun, ó sì sọ pé: “Màá jáde lọ bíi ti tẹ́lẹ̀,+ màá sì gbọn ara mi yọ.” Àmọ́ kò mọ̀ pé Jèhófà ti fi òun sílẹ̀. 21 Àwọn Filísínì mú un, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀. Wọ́n mú un wá sí Gásà, wọ́n sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é, ó wá ń lọ ọkà nínú ẹ̀wọ̀n. 22 Àmọ́ irun orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í hù pa dà lẹ́yìn tí wọ́n gé e.+
23 Àwọn alákòóso Filísínì kóra jọ láti rú ẹbọ ńlá sí Dágónì+ ọlọ́run wọn, kí wọ́n sì ṣe àjọyọ̀, torí wọ́n ń sọ pé: “Ọlọ́run wa ti fi Sámúsìn ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́!” 24 Nígbà tí àwọn èèyàn náà rí i, wọ́n yin ọlọ́run wọn, wọ́n sì sọ pé: “Ọlọ́run wa ti fi ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́, ẹni tó run ilẹ̀ wa+ tó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa.”+
25 Torí pé inú wọn ń dùn, wọ́n sọ pé: “Ẹ pe Sámúsìn wá kó wá dá wa lára yá.” Wọ́n wá pe Sámúsìn jáde látinú ẹ̀wọ̀n kó lè dá wọn lára yá; wọ́n mú un dúró sáàárín àwọn òpó. 26 Sámúsìn sọ fún ọmọkùnrin tó dì í lọ́wọ́ mú pé: “Jẹ́ kí n fọwọ́ kan àwọn òpó tó gbé ilé yìí ró, kí n lè fara tì wọ́n.” 27 (Ó ṣẹlẹ̀ pé tọkùnrin tobìnrin ló kún inú ilé náà. Gbogbo àwọn alákòósò Filísínì ló wà níbẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin àti obìnrin ló wà lórí òrùlé tí wọ́n ń wo bí Sámúsìn ṣe ń dá wọn lára yá.)
28 Sámúsìn+ wá ké pe Jèhófà pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, jọ̀ọ́ rántí mi, jọ̀ọ́ fún mi lókun+ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo yìí, ìwọ Ọlọ́run, kí o sì jẹ́ kí n gbẹ̀san ọ̀kan nínú ojú mi méjèèjì+ lára àwọn Filísínì.”
29 Ni Sámúsìn bá fọwọ́ ti òpó méjèèjì tó wà láàárín, èyí tó gbé ilé náà ró, ó gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé ọ̀kan, ó sì gbé ọwọ́ òsì rẹ̀ lé èkejì. 30 Sámúsìn kígbe pé: “Jẹ́ kí n* kú pẹ̀lú àwọn Filísínì.” Ó wá fi gbogbo agbára rẹ̀ tì í, ilé náà sì wó lu àwọn alákòóso náà àti gbogbo àwọn èèyàn tó wà nínú rẹ̀.+ Àwọn tó pa nígbà tó kú pọ̀ ju àwọn tó pa nígbà tó wà láàyè lọ.+
31 Lẹ́yìn náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé bàbá rẹ̀ wá gbé e kúrò níbẹ̀. Wọ́n sì gbé e gòkè wá, wọ́n sin ín sáàárín Sórà+ àti Éṣítáólì, ní ibojì Mánóà+ bàbá rẹ̀. Ogún (20) ọdún+ ló fi ṣe onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì.
17 Ọkùnrin kan wà ní agbègbè olókè Éfúrémù+ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà. 2 Ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún (1,100) ẹyọ fàdákà tí wọ́n kó lọ́dọ̀ rẹ, tí mo gbọ́ tí o gégùn-ún nípa rẹ̀, wò ó! fàdákà náà wà lọ́wọ́ mi. Èmi ni mo kó o.” Ni ìyá rẹ̀ bá sọ pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ, ọmọ mi.” 3 Ó wá kó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún (1,100) ẹyọ fàdákà náà pa dà fún ìyá rẹ̀, àmọ́ ìyá rẹ̀ sọ pé: “Ó dájú pé màá ya fàdákà náà sí mímọ́ fún Jèhófà látọwọ́ mi, kí ọmọ mi lè fi ṣe ère gbígbẹ́ àti ère onírin.*+ Mo fún ọ pa dà báyìí.”
4 Lẹ́yìn tó dá fàdákà náà pa dà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ mú igba (200) ẹyọ fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà. Ó ṣe ère gbígbẹ́ àti ère onírin;* wọ́n sì gbé e sínú ilé Míkà. 5 Ọkùnrin tó ń jẹ́ Míkà yìí ní ilé kan tó kó àwọn ọlọ́run rẹ̀ sí, ó ṣe éfódì kan+ àti àwọn ère tẹ́ráfímù,*+ ó sì yan* ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ pé kó jẹ́ àlùfáà rẹ̀.+ 6 Nígbà yẹn, kò sí ọba ní Ísírẹ́lì.+ Kálukú ń ṣe ohun tó tọ́ lójú ara rẹ̀.*+
7 Ọ̀dọ́kùnrin kan wà tó jẹ́ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà, látinú ìdílé Júdà. Ọmọ Léfì+ ni, ó sì ti ń gbé níbẹ̀ fúngbà díẹ̀. 8 Ọkùnrin náà kúrò nílùú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, ó ń wá ibi tó máa gbé. Bó ṣe ń rìnrìn àjò lọ, ó dé agbègbè olókè Éfúrémù, ní ilé Míkà.+ 9 Míkà wá bi í pé: “Ibo lo ti wá?” Ó fèsì pé: “Ọmọ Léfì ni mí, láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, mò ń wá ibi tí mo lè máa gbé.” 10 Míkà wá sọ fún un pé: “Dúró sọ́dọ̀ mi, kí o di bàbá* àti àlùfáà fún mi. Màá máa fún ọ ní ẹyọ fàdákà mẹ́wàá lọ́dún, pẹ̀lú àwọn aṣọ àti oúnjẹ tí wàá máa jẹ.” Ọmọ Léfì náà sì wọlé. 11 Bí ọmọ Léfì náà ṣe gbà láti máa gbé lọ́dọ̀ ọkùnrin náà nìyẹn, ọ̀dọ́kùnrin náà sì wá dà bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀. 12 Yàtọ̀ síyẹn, Míkà fiṣẹ́ lé ọmọ Léfì náà lọ́wọ́* pé kó di àlùfáà rẹ̀,+ ó sì ń gbé ní ilé Míkà. 13 Míkà wá sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé Jèhófà máa ṣe rere sí mi, torí pé ọmọ Léfì ti di àlùfáà mi.”
18 Nígbà yẹn, kò sí ọba ní Ísírẹ́lì.+ Ní àkókò yẹn, ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì+ ń wá ilẹ̀* tí wọ́n á máa gbé, torí pé wọn ò tíì rí ogún gbà láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.+
2 Àwọn ọmọ Dánì rán ọkùnrin márùn-ún látinú ìdílé wọn, àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti Sórà àti Éṣítáólì+ pé kí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.” Nígbà tí wọ́n dé agbègbè olókè Éfúrémù, ní ilé Míkà,+ wọ́n sun ibẹ̀ mọ́jú. 3 Nígbà tí wọ́n dé tòsí ilé Míkà, wọ́n dá ohùn* ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ ọmọ Léfì náà mọ̀, wọ́n wá lọ bá a, wọ́n sì bi í pé: “Ta ló mú ọ wá síbí? Kí lò ń ṣe níbí? Kí ló dá ọ dúró síbí?” 4 Ó dá wọn lóhùn pé: “Báyìí báyìí ni Míkà ṣe fún mi, ó sì gbà mí pé kí n máa ṣe àlùfáà òun.”+ 5 Wọ́n wá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, bá wa bi Ọlọ́run bóyá ìrìn àjò wa máa yọrí sí rere.” 6 Àlùfáà náà sọ fún wọn pé: “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Jèhófà wà pẹ̀lú yín lẹ́nu ìrìn àjò yín.”
7 Àwọn ọkùnrin márùn-ún náà wá ń bá ìrìn àjò wọn lọ, wọ́n sì dé Láíṣì.+ Wọ́n rí bí àwọn tó ń gbé ibẹ̀ kò ṣe gbára lé ẹnikẹ́ni bíi ti àwọn ọmọ Sídónì. Èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni wọ́n, wọn kì í fura,+ kò sì sí aninilára kankan tó wá jẹ gàba lé wọn lórí ní ilẹ̀ náà láti yọ wọ́n lẹ́nu. Wọ́n jìnnà gan-an sí àwọn ọmọ Sídónì, wọn kò sì bá àwọn míì da nǹkan pọ̀.
8 Nígbà tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Sórà àti Éṣítáólì,+ àwọn arákùnrin wọn bi wọ́n pé: “Báwo lọ̀hún?” 9 Wọ́n fèsì pé: “Ẹ jẹ́ ká lọ gbógun jà wọ́n, torí a ti rí i pé ilẹ̀ náà dáa gan-an. Kí ló dé tí ẹ̀ ń lọ́ra? Ẹ má fi falẹ̀, ẹ lọ gba ilẹ̀ náà. 10 Tí ẹ bá dé ibẹ̀, ẹ máa rí àwọn èèyàn tí kì í fura,+ ilẹ̀ náà sì fẹ̀. Ọlọ́run ti fi lé yín lọ́wọ́, kò sóhun tí ẹ fẹ́ láyé yìí tí ẹ ò ní rí níbẹ̀.”+
11 Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin tó dira ogun látinú ìdílé àwọn ọmọ Dánì wá gbéra láti Sórà àti Éṣítáólì.+ 12 Wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Kiriati-jéárímù+ ní Júdà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibi tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Kiriati-jéárímù yẹn ní Mahane-dánì*+ títí dòní. 13 Wọ́n kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè olókè Éfúrémù, wọ́n sì dé ilé Míkà.+
14 Àwọn ọkùnrin márùn-ún tó lọ ṣe amí ilẹ̀ Láíṣì+ wá sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé éfódì, àwọn ère tẹ́ráfímù,* ère gbígbẹ́ àti ère onírin*+ wà nínú àwọn ilé yìí? Ẹ ronú ohun tó yẹ kí ẹ ṣe.” 15 Wọ́n wá dúró níbẹ̀, wọ́n sì wá sí ilé ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ ọmọ Léfì+ náà ní ilé Míkà, wọ́n béèrè àlàáfíà rẹ̀. 16 Ní gbogbo ìgbà yẹn, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin látinú ẹ̀yà Dánì+ tó dira ogun dúró síbi àbáwọ ẹnubodè. 17 Àwọn ọkùnrin márùn-ún tó lọ ṣe amí ilẹ̀ náà+ wá wọlé lọ kó ère gbígbẹ́, éfódì,+ àwọn ère tẹ́ráfímù*+ àti ère onírin*+ náà. (Àlùfáà náà+ dúró síbi àbáwọ ẹnubodè náà pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ọkùnrin tó dira ogun.) 18 Wọ́n wọnú ilé Míkà, wọ́n sì kó ère gbígbẹ́, éfódì, àwọn ère tẹ́ráfímù* àti ère onírin* náà. Àlùfáà náà bi wọ́n pé: “Kí lẹ̀ ń ṣe yìí?” 19 Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé: “Dákẹ́. Fọwọ́ bo ẹnu rẹ, kí o sì tẹ̀ lé wa, kí o lè di bàbá* àti àlùfáà fún wa. Èwo ló dáa jù nínú kí o jẹ́ àlùfáà fún ilé ọkùnrin kan+ tàbí kí o di àlùfáà fún ẹ̀yà àti ìdílé kan ní Ísírẹ́lì?”+ 20 Ọ̀rọ̀ yẹn tẹ́ àlùfáà náà lọ́rùn, ó kó éfódì, àwọn ère tẹ́ráfímù* àti ère gbígbẹ́ náà,+ ó sì tẹ̀ lé àwọn èèyàn náà lọ.
21 Wọ́n wá ṣẹ́rí pa dà kí wọ́n lè máa lọ, wọ́n kó àwọn ọmọdé, àwọn ẹran ọ̀sìn àti àwọn ohun tó ṣeyebíye síwájú. 22 Wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Míkà nígbà tí àwọn ọkùnrin tó ń gbé ní àwọn ilé tó wà nítòsí ilé Míkà kóra jọ, tí wọ́n sì lé àwọn ọmọ Dánì bá. 23 Nígbà tí wọ́n ké pe àwọn ọmọ Dánì, wọ́n yíjú pa dà, wọ́n sì sọ fún Míkà pé: “Kí ló ṣẹlẹ̀? Kí ló dé tí ẹ lọ kóra yín jọ?” 24 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ti kó àwọn ọlọ́run mi tí mo ṣe, ẹ tún mú àlùfáà lọ. Kí ló kù tí mo ní? Ṣé ó wá yẹ kí ẹ máa bi mí pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’” 25 Àwọn ọmọ Dánì sọ fún un pé: “Má pariwo mọ́ wa; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ọkùnrin tínú ń bí* lè lù ọ́ bolẹ̀, ẹ̀mí* rẹ àti ti agbo ilé rẹ sì lè lọ sí i.” 26 Àwọn ọmọ Dánì wá ń bá tiwọn lọ; nígbà tí Míkà rí i pé wọ́n lágbára ju òun lọ, ó pa dà, ó sì lọ sí ilé rẹ̀.
27 Lẹ́yìn tí wọ́n kó àwọn ohun tí Míkà ṣe, títí kan àlùfáà rẹ̀, wọ́n lọ sí Láíṣì,+ lọ́dọ̀ àwọn èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, tí wọn kì í fura.+ Wọ́n fi idà ṣá wọn balẹ̀, wọ́n sì dáná sun ìlú náà. 28 Kò sẹ́ni tó lè gbà wọ́n sílẹ̀ torí pé ó jìnnà sí Sídónì, wọn kì í bá àwọn míì da nǹkan pọ̀, àfonífojì* tó jẹ́ ti Bẹti-réhóbù+ ni ìlú náà sì wà. Wọ́n wá tún ìlú náà kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. 29 Bákan náà, wọ́n sọ ìlú náà ní Dánì,+ ìyẹn Dánì orúkọ bàbá wọn, ẹni tí wọ́n bí fún Ísírẹ́lì.+ Àmọ́ Láíṣì ni ìlú náà ń jẹ́ tẹ́lẹ̀.+ 30 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Dánì gbé ère gbígbẹ́ náà+ kalẹ̀ fún ara wọn, Jónátánì+ ọmọ Gẹ́ṣómù,+ ọmọ Mósè àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì di àlùfáà fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì títí di ọjọ́ tí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà fi lọ sí ìgbèkùn. 31 Wọ́n gbé ère gbígbẹ́ tí Míkà ṣe kalẹ̀, ó sì wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tí ilé Ọlọ́run tòótọ́ fi wà ní Ṣílò.+
19 Nígbà yẹn, tí kò sí ọba ní Ísírẹ́lì,+ ọmọ Léfì kan tó ń gbé apá ibi tó jìnnà ní agbègbè olókè Éfúrémù+ lákòókò yẹn fẹ́ wáhàrì* kan láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà. 2 Àmọ́ wáhàrì rẹ̀ dalẹ̀ rẹ̀, ó sì fi ọkùnrin náà sílẹ̀, ó wá pa dà sí ilé bàbá rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà. Oṣù mẹ́rin ló fi wà níbẹ̀. 3 Ọkọ rẹ̀ wá lọ bá a kó lè rọ̀ ọ́ pé kó pa dà wá; ó mú ìránṣẹ́kùnrin rẹ̀ àtàwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ dání. Obìnrin náà wá mú un wá sínú ilé bàbá rẹ̀. Nígbà tí bàbá rẹ̀ rí ọkùnrin náà, inú rẹ̀ dùn pé òun rí i. 4 Bàbá ìyàwó rẹ̀, ìyẹn bàbá ọ̀dọ́bìnrin náà wá mú kó dúró ti òun fún ọjọ́ mẹ́ta; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, ó sì ń sun ibẹ̀ mọ́jú.
5 Nígbà tí wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kẹrin kí wọ́n lè máa lọ, bàbá ọ̀dọ́bìnrin náà sọ fún ọkọ ọmọ rẹ̀ pé: “Jẹun kí o lè lókun,* kí o tó máa lọ.” 6 Torí náà, wọ́n jókòó, àwọn méjèèjì jọ jẹun, wọ́n sì mu; lẹ́yìn náà, bàbá ọ̀dọ́bìnrin náà sọ fún ọkùnrin náà pé: “Jọ̀ọ́, sùn síbí mọ́jú, kí o sì gbádùn ara rẹ.”* 7 Nígbà tí ọkùnrin náà dìde kó lè máa lọ, bàbá ìyàwó rẹ̀ ń bẹ̀ ẹ́ ṣáá, ló bá tún sun ibẹ̀ mọ́jú.
8 Nígbà tó dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ karùn-ún kó lè máa lọ, bàbá ọ̀dọ́bìnrin náà sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, jẹun kí o lè lókun.”* Wọ́n wá ń fi nǹkan falẹ̀ títí ọjọ́ fi lọ, àwọn méjèèjì ò kúrò nídìí oúnjẹ. 9 Nígbà tí ọkùnrin náà dìde kí òun àti wáhàrì rẹ̀ pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ̀ lè máa lọ, bàbá ìyàwó rẹ̀, ìyẹn bàbá ọ̀dọ́bìnrin náà, sọ fún un pé: “Wò ó! Ilẹ̀ ò ní pẹ́ ṣú báyìí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sùn síbí mọ́jú. Ilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣú. Sùn síbí mọ́jú, kí o sì gbádùn ara rẹ. Tó bá di ọ̀la, ẹ lè dìde ní àárọ̀ kùtù kí ẹ máa lọ, kí o sì pa dà sí ilé* rẹ.” 10 Àmọ́ ọkùnrin náà ò tún fẹ́ sun ibẹ̀ mọ́jú, torí náà, ó gbéra, ó sì rìnrìn àjò títí dé Jébúsì, ìyẹn Jerúsálẹ́mù.+ Ó mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí wọ́n de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́* dání pẹ̀lú wáhàrì rẹ̀ àti ìránṣẹ́ rẹ̀.
11 Nígbà tí wọ́n dé tòsí Jébúsì, ilẹ̀ ti ń ṣú lọ. Ìránṣẹ́ náà wá bi ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ṣé ká dúró ní ìlú àwọn ará Jébúsì yìí ká sì sun ibẹ̀ mọ́jú?” 12 Àmọ́ ọ̀gá rẹ̀ sọ fún un pé: “Kò yẹ ká dúró ní ìlú àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. Ká máa lọ títí a fi máa dé Gíbíà.”+ 13 Ó sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Máa bọ̀, jẹ́ ká gbìyànjú láti dé ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà; a máa sun Gíbíà tàbí Rámà+ mọ́jú.” 14 Wọ́n wá ń bá ìrìn àjò wọn lọ, oòrùn sì ti ń wọ̀ nígbà tí wọ́n ń sún mọ́ Gíbíà, tó jẹ́ ti Bẹ́ńjámínì.
15 Wọ́n wá dúró níbẹ̀, wọ́n sì wọlé lọ sí Gíbíà kí wọ́n lè sun ibẹ̀ mọ́jú. Lẹ́yìn tí wọ́n wọlé, wọ́n jókòó sí ojúde ìlú náà, àmọ́ kò sí ẹni tó gbà wọ́n sílé kí wọ́n lè sun ibẹ̀ mọ́jú.+ 16 Nígbà tó yá, ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, bàbá arúgbó kan ń ti oko bọ̀ níbi tó ti lọ ṣiṣẹ́. Agbègbè olókè Éfúrémù+ ló ti wá, ó sì ń gbé fúngbà díẹ̀ ní Gíbíà; àmọ́ ọmọ Bẹ́ńjámínì+ ni àwọn tó ń gbé ìlú náà. 17 Nígbà tó wòkè tó sì rí arìnrìn-àjò náà ní ojúde ìlú, bàbá arúgbó náà bi í pé: “Ibo lo ti ń bọ̀, ibo lo sì ń lọ?” 18 Ó fèsì pé: “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà la ti ń bọ̀, a sì ń lọ síbi tó jìnnà ní agbègbè olókè Éfúrémù, níbi tí mo ti wá. Mo lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà,+ mo sì ń lọ sí ilé Jèhófà,* àmọ́ ẹnì kankan ò gbà mí sílé. 19 A ní pòròpórò àti oúnjẹ ẹran tó máa tó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ wa, a sì ní oúnjẹ+ àti wáìnì tí èmi, obìnrin náà àti ìránṣẹ́ wa máa jẹ. A ò ṣaláìní ohunkóhun.” 20 Àmọ́ bàbá arúgbó náà sọ pé: “Àlàáfíà fún ọ! Jẹ́ kí n pèsè ohunkóhun tí o bá nílò. Ṣáà má sun ojúde ìlú mọ́jú.” 21 Ó wá mú un wá sínú ilé rẹ̀, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ní oúnjẹ.* Lẹ́yìn náà, wọ́n fọ ẹsẹ̀ wọn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.
22 Bí wọ́n ṣe ń gbádùn ara wọn, àwọn ọkùnrin kan tí kò ní láárí nínú ìlú yí ilé náà ká, wọ́n sì ń gbá ilẹ̀kùn, wọ́n ń sọ fún bàbá arúgbó tó ni ilé náà pé: “Mú ọkùnrin tó wá sínú ilé rẹ jáde, ká lè bá a lò pọ̀.”+ 23 Ni onílé bá jáde lọ sọ fún wọn pé: “Rárá o, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ má hùwà burúkú. Ẹ jọ̀ọ́, àlejò ni ọkùnrin tó wà nínú ilé mi yìí. Ẹ má hùwà tó ń tini lójú yìí. 24 Ọmọbìnrin mi tí kò tíì mọ ọkùnrin àti wáhàrì ọkùnrin náà nìyí. Ẹ jẹ́ kí n mú wọn jáde, kí ẹ sì bá wọn lò pọ̀ tó bá jẹ́ ohun tí ẹ fẹ́ nìyẹn.*+ Àmọ́ ẹ má hùwà tó ń tini lójú yìí sí ọkùnrin yìí.”
25 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà kò dá a lóhùn. Torí náà, ọkùnrin náà mú wáhàrì rẹ̀+ jáde fún wọn. Wọ́n fipá bá a lò pọ̀, wọ́n sì ṣe obìnrin náà ṣúkaṣùka ní gbogbo òru títí di àárọ̀. Wọ́n wá ní kó máa lọ nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀. 26 Obìnrin náà dé ní àárọ̀ kùtù, ó sì ṣubú sí ẹnu ọ̀nà ilé ọkùnrin tí ọ̀gá rẹ̀ wà, ó dùbúlẹ̀ síbẹ̀ títí ilẹ̀ fi mọ́. 27 Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ dìde ní àárọ̀, tó ṣí ilẹ̀kùn ilé náà kó lè máa bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó rí obìnrin náà, wáhàrì rẹ̀, tó dùbúlẹ̀ sí ẹnu ọ̀nà ilé náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ síbi àbáwọlé. 28 Ó wá sọ fún un pé: “Dìde, jẹ́ ká lọ.” Àmọ́ kò dáhùn. Ọkùnrin náà wá gbé e sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì forí lé ilé rẹ̀.
29 Nígbà tó dé ilé rẹ̀, ó mú ọ̀bẹ ìpẹran, ó wá mú wáhàrì rẹ̀, ó sì gé e sí ọ̀nà méjìlá (12), ó wá fi ọ̀kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní Ísírẹ́lì. 30 Gbogbo àwọn tó rí i sọ pé: “Irú èyí ò ṣẹlẹ̀ rí, a ò sì rí irú rẹ̀ rí látọjọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì títí dòní. Ẹ rò ó wò,* ẹ gbà wá nímọ̀ràn,+ kí ẹ sì sọ ohun tí a máa ṣe fún wa.”
20 Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Dánì+ títí lọ dé Bíá-ṣébà àti ilẹ̀ Gílíádì,+ gbogbo àpéjọ náà sì kóra jọ sójú kan* níwájú Jèhófà ní Mísípà.+ 2 Àwọn ìjòyè àwọn èèyàn náà àti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì dúró sí àyè wọn nínú ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn tó sì ń lo idà.+
3 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì gbọ́ pé àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti lọ sí Mísípà.
Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì sọ pé: “Ẹ sọ fún wa, báwo ni nǹkan búburú yìí ṣe ṣẹlẹ̀?”+ 4 Ọmọ Léfì,+ tó jẹ́ ọkọ obìnrin tí wọ́n pa náà wá dáhùn pé: “Èmi àti wáhàrì mi wá sun Gíbíà+ ti Bẹ́ńjámínì mọ́jú. 5 Ni àwọn tó ń gbé* Gíbíà bá dìde sí mi, wọ́n sì yí ilé náà ká ní òru. Èmi ni wọ́n fẹ́ pa, àmọ́ dípò ìyẹn, wáhàrì* mi ni wọ́n fipá bá lò pọ̀, ó sì kú.+ 6 Mo wá mú òkú wáhàrì mi, mo gé e sí wẹ́wẹ́, mo sì fi àwọn ègé náà ránṣẹ́ sí gbogbo ilẹ̀ tí Ísírẹ́lì jogún,+ torí ìwà burúkú àti ìwà tó ń dójú tini ni wọ́n hù ní Ísírẹ́lì. 7 Gbogbo ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, ẹ sọ ìmọ̀ràn+ yín àti ohun tí ẹ rò.”
8 Gbogbo àwọn èèyàn náà wá dìde, wọ́n fohùn ṣọ̀kan* pé: “Ìkankan nínú wa ò ní lọ sí àgọ́ rẹ̀, a ò sì ní pa dà sí ilé wa. 9 Ohun tí a máa ṣe sí Gíbíà nìyí: A máa ṣẹ́ kèké láti lọ bá a jà.+ 10 A máa mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún (100) látinú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì. A sì máa mú ọgọ́rùn-ún (100) nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) àti ẹgbẹ̀rún (1,000) nínú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) pé kí wọ́n pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun náà, kí wọ́n lè gbógun ja Gíbíà ti Bẹ́ńjámínì, torí ìwà tó ń dójú tini tí wọ́n hù ní Ísírẹ́lì.” 11 Gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì bá kóra jọ, wọ́n fìmọ̀ ṣọ̀kan* bí ọmọ ẹgbẹ́ láti lọ gbógun ja ìlú náà.
12 Àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì wá rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo àwọn ọkùnrin ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì pé: “Irú ohun burúkú wo ló ṣẹlẹ̀ láàárín yín yìí? 13 Ó yá, ẹ fi àwọn ọkùnrin Gíbíà+ tí kò ní láárí yẹn lé wa lọ́wọ́, ká lè pa wọ́n, ká sì mú ohun tí kò dáa kúrò ní Ísírẹ́lì.”+ Àmọ́ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì kò fetí sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ arákùnrin wọn.
14 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì wá kóra jọ látinú àwọn ìlú sí Gíbíà, kí wọ́n lè lọ bá àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jà. 15 Lọ́jọ́ yẹn, àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì kó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26,000) ọkùnrin tó ń lo idà jọ látinú àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí ọgọ́rùn-ún méje (700) ọkùnrin tí wọ́n yàn láti Gíbíà. 16 Ọgọ́rùn-ún méje (700) ọkùnrin tí wọ́n yàn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́wọ́ òsì wà lára àwọn ọmọ ogun yìí. Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ló lè fi kànnàkànnà ju òkúta ba ìbú fọ́nrán irun, tí kò sì ní tàsé.
17 Yàtọ̀ sí Bẹ́ńjámínì, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin tó ń lo idà+ jọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì mọ ogun jà dáadáa. 18 Wọ́n gbéra, wọ́n sì lọ sí Bẹ́tẹ́lì láti wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì wá sọ pé: “Ta ni kó ṣáájú nínú wa láti lọ bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì jà?” Jèhófà fèsì pé: “Júdà ni kó ṣáájú.”
19 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dìde ní àárọ̀, wọ́n sì pàgọ́ ti Gíbíà.
20 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wá jáde lọ gbógun ja Bẹ́ńjámínì; wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun jà wọ́n ní Gíbíà. 21 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì wá jáde láti Gíbíà, wọ́n sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ọkùnrin Ísírẹ́lì lọ́jọ́ yẹn. 22 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì fi hàn pé àwọn nígboyà, wọ́n bá tún tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun jà wọ́n ní ibì kan náà bíi ti ọjọ́ àkọ́kọ́. 23 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá gòkè lọ, wọ́n sì sunkún níwájú Jèhófà títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà pé: “Ṣé ká tún lọ bá àwọn arákùnrin wa, àwọn èèyàn Bẹ́ńjámínì jà?”+ Jèhófà fèsì pé: “Ẹ lọ bá wọn jà.”
24 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá sún mọ́ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ní ọjọ́ kejì. 25 Ni Bẹ́ńjámínì bá jáde wá bá wọn láti Gíbíà lọ́jọ́ kejì, wọ́n sì pa ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) míì tí gbogbo wọn ń lo idà lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 26 Torí náà, gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n sunkún, wọ́n sì jókòó síbẹ̀ níwájú Jèhófà,+ wọ́n gbààwẹ̀+ lọ́jọ́ yẹn títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì rú àwọn ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ níwájú Jèhófà. 27 Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà,+ torí àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́ wà níbẹ̀ nígbà yẹn. 28 Fíníhásì+ ọmọ Élíásárì, ọmọ Áárónì, ló ń ṣiṣẹ́* níwájú rẹ̀ nígbà yẹn. Wọ́n béèrè pé: “Ṣé ká tún lọ bá àwọn arákùnrin wa, àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì jà, àbí ká má lọ mọ́?”+ Jèhófà fèsì pé: “Ẹ lọ, torí ọ̀la ni màá fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.” 29 Ísírẹ́lì wá ní kí àwọn ọkùnrin lọ lúgọ+ yí Gíbíà ká.
30 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì jà ní ọjọ́ kẹta, wọ́n sì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun ja Gíbíà bíi ti tẹ́lẹ̀.+ 31 Nígbà tí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì jáde lọ bá àwọn ọmọ ogun náà, wọ́n tàn wọ́n jìnnà sí ìlú náà.+ Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun jà wọ́n bíi ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sì pa lára àwọn ọkùnrin náà láwọn ojú ọ̀nà, tí ọ̀kan lọ sí Bẹ́tẹ́lì tí èkejì sì lọ sí Gíbíà, nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọkùnrin Ísírẹ́lì ni wọ́n pa sínú pápá gbalasa.+ 32 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì wá sọ pé: “A ti ń ṣẹ́gun wọn bíi ti tẹ́lẹ̀.”+ Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé: “A máa sá fún wọn, a sì máa tàn wọ́n jìnnà sí ìlú náà wá sí ojú ọ̀nà.” 33 Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wá dìde láwọn ibi tí wọ́n wà, wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ní Baali-támárì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lúgọ sì jáde láwọn ibi tí wọ́n wà nítòsí Gíbíà. 34 Bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin tí wọ́n yàn látinú gbogbo Ísírẹ́lì ṣe wá síwájú Gíbíà nìyẹn, ìjà náà sì le gan-an. Àmọ́ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ò mọ̀ pé àjálù rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí àwọn.
35 Jèhófà ṣẹ́gun Bẹ́ńjámínì+ níwájú Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ó lé ọgọ́rùn-ún kan (25,100) ọkùnrin Bẹ́ńjámínì tí wọ́n ń lo idà+ ni Ísírẹ́lì pa lọ́jọ́ yẹn.
36 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ti rò pé àwọn máa ṣẹ́gun àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń sá fún Bẹ́ńjámínì,+ àmọ́ ohun tó mú kí wọ́n sá ni pé ọkàn wọn balẹ̀ torí àwọn tó lúgọ láti gbógun ja Gíbíà.+ 37 Àwọn tó lúgọ náà ò fi nǹkan falẹ̀ rárá, wọ́n yára sún mọ́ Gíbíà. Wọ́n wá pín ara wọn yí ká ìlú náà, wọ́n sì fi idà ṣá gbogbo ìlú náà balẹ̀.
38 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti ṣètò pé kí àwọn ọkùnrin tó lúgọ sí tòsí ìlú náà mú kí èéfín rú láti ibẹ̀, kó lè jẹ́ àmì fún wọn.
39 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́rí pa dà lójú ogun, àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun jà wọ́n, wọ́n sì pa nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọkùnrin Ísírẹ́lì,+ wọ́n wá sọ pé: “Ó dájú pé a tún ti ń ṣẹ́gun wọn bíi ti tẹ́lẹ̀.”+ 40 Àmọ́ èéfín tí wọ́n fi ṣe àmì náà bẹ̀rẹ̀ sí í rú sókè látinú ìlú náà, ó rí bí òpó. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì yíjú pa dà, wọ́n rí i pé gbogbo ìlú náà ti ń jóná, èéfín rẹ̀ sì ń lọ sókè. 41 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wá yíjú pa dà, jìnnìjìnnì sì bá àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì, torí wọ́n rí i pé àjálù ti dé bá àwọn. 42 Torí náà, wọ́n sá fún àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì gba ọ̀nà aginjù, àmọ́ Ísírẹ́lì gbógun tẹ̀ lé wọn; àwọn ọkùnrin tó jáde látinú àwọn ìlú náà dara pọ̀ mọ́ wọn láti bá wọn jà. 43 Wọ́n yí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ká. Wọ́n sì ń lé wọn, wọn ò dẹ̀yìn lẹ́yìn wọn. Wọ́n ṣẹ́gun wọn níwájú Gíbíà gangan, lápá ìlà oòrùn. 44 Níkẹyìn, ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) ọkùnrin Bẹ́ńjámínì ló kú, jagunjagun tó lákíkanjú+ ni gbogbo wọn.
45 Àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì ṣẹ́rí pa dà, wọ́n sì sá lọ sí aginjù, níbi àpáta Rímónì.+ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa* ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) nínú wọn lójú ọ̀nà, wọ́n sì ń lé wọn títí dé Gídómù; wọ́n wá pa ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọkùnrin sí i. 46 Gbogbo àwọn èèyàn Bẹ́ńjámínì tó kú lọ́jọ́ yẹn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ọkùnrin tó ń lo idà,+ jagunjagun tó lákíkanjú ni gbogbo wọn. 47 Àmọ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) lára wọn sá lọ sí aginjù, níbi àpáta Rímónì, wọ́n sì dúró sórí àpáta Rímónì fún oṣù mẹ́rin.
48 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yíjú pa dà, wọ́n sì gbógun ja àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, wọ́n fi idà pa àwọn tó wà nínú ìlú, látorí èèyàn dórí ẹran ọ̀sìn, gbogbo ohun tó ṣẹ́ kù. Bákan náà, gbogbo ìlú tí wọ́n rí lójú ọ̀nà ni wọ́n dáná sun.
21 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti búra ní Mísípà+ pé: “Ìkankan nínú wa ò ní fún ọkùnrin kankan tó jẹ́ ọmọ Bẹ́ńjámínì ní ọmọbìnrin rẹ̀ pé kó fi ṣe aya.”+ 2 Torí náà, àwọn èèyàn náà wá sí Bẹ́tẹ́lì,+ wọ́n sì jókòó síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run tòótọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n ń ké, wọ́n sì ń sunkún gidigidi. 3 Wọ́n ń sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí ló dé tí èyí fi ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì? Kí ló dé tí ẹ̀yà Ísírẹ́lì fi dín ọ̀kan lónìí?” 4 Lọ́jọ́ kejì, àwọn èèyàn náà dìde ní àárọ̀ kùtù, wọ́n sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, láti rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+
5 Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì wá sọ pé: “Èwo nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni kò wá láti pé jọ síwájú Jèhófà?” torí wọ́n ti ṣe ìbúra tó lágbára pé ṣe ni wọ́n máa pa ẹnikẹ́ni tí kò bá wá sọ́dọ̀ Jèhófà ní Mísípà. 6 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì banú jẹ́ torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bẹ́ńjámínì arákùnrin wọn. Wọ́n ní: “A ti gé ẹ̀yà kan kúrò ní Ísírẹ́lì lónìí. 7 Báwo la ṣe máa rí ìyàwó fún àwọn tó ṣẹ́ kù, torí a ti fi Jèhófà búra+ pé a ò ní fún wọn ní ìkankan nínú àwọn ọmọbìnrin wa pé kí wọ́n fi ṣe aya?”+
8 Wọ́n béèrè pé: “Èwo nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni kò wá sọ́dọ̀ Jèhófà ní Mísípà?”+ Ó ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kankan ò wá láti Jabeṣi-gílíádì sínú ibùdó tí ìjọ náà wà. 9 Nígbà tí wọ́n ka àwọn èèyàn náà, wọ́n rí i pé ìkankan nínú àwọn tó ń gbé ní Jabeṣi-gílíádì kò sí níbẹ̀. 10 Àpéjọ náà wá rán ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) lára àwọn ọkùnrin tó lágbára jù lọ síbẹ̀. Wọ́n pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ lọ fi idà pa àwọn tó ń gbé ní Jabeṣi-gílíádì, títí kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.+ 11 Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Kí ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tó ti bá ọkùnrin lò pọ̀ run.” 12 Láàárín àwọn tó ń gbé ní Jabeṣi-gílíádì, wọ́n rí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọmọbìnrin tí wọ́n jẹ́ wúńdíá, tí wọn ò bá ọkùnrin lò pọ̀ rí. Wọ́n sì kó wọn wá sí ibùdó tó wà ní Ṣílò,+ èyí tó wà ní ilẹ̀ Kénáánì.
13 Gbogbo àpéjọ náà wá ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì tó wà lórí àpáta Rímónì,+ wọ́n sì bá wọn ṣàdéhùn àlàáfíà. 14 Ìgbà yẹn ni Bẹ́ńjámínì wá pa dà. Wọ́n sì fún wọn ní àwọn obìnrin tí wọ́n dá ẹ̀mí wọn sí nínú àwọn obìnrin Jabeṣi-gílíádì,+ àmọ́ iye tí wọ́n rí yẹn ò kárí wọn. 15 Àwọn èèyàn náà sì banú jẹ́ torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bẹ́ńjámínì,+ torí Jèhófà ti pín ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níyà. 16 Àwọn àgbààgbà àpéjọ náà sọ pé: “Báwo la ṣe máa rí ìyàwó fún àwọn ọkùnrin yòókù, torí pé gbogbo obìnrin Bẹ́ńjámínì ló ti pa run?” 17 Wọ́n fèsì pé: “Ó yẹ kí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì tó yè bọ́ ní ogún, kí ẹ̀yà kan má bàa pa run ní Ísírẹ́lì. 18 Àmọ́, a ò ní lè fún wọn ní àwọn ọmọbìnrin wa pé kí wọ́n fi ṣe aya, torí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti búra pé: ‘Ègún ni fún ẹni tó bá fún Bẹ́ńjámínì níyàwó.’”+
19 Wọ́n wá sọ pé: “Ẹ wò ó! Àjọyọ̀ Jèhófà tí a máa ń ṣe lọ́dọọdún máa wáyé ní Ṣílò,+ èyí tó wà ní àríwá Bẹ́tẹ́lì, lápá ìlà oòrùn ọ̀nà tó lọ láti Bẹ́tẹ́lì sí Ṣékémù àti gúúsù Lẹ́bónà.” 20 Torí náà, wọ́n pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì pé: “Ẹ lọ lúgọ sínú àwọn ọgbà àjàrà. 21 Tí ẹ bá sì rí àwọn ọ̀dọ́bìnrin* Ṣílò tí wọ́n ń jáde wá bá àwọn yòókù jó ijó àjóyípo, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín jáde látinú àwọn ọgbà àjàrà, kí ẹ sì sáré gbé ìkọ̀ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́bìnrin Ṣílò láti fi ṣe aya. Kí ẹ wá pa dà sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì. 22 Tí àwọn bàbá wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn bá sì wá fi ẹjọ́ sùn wá, a máa sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣàánú wa torí tiwọn, torí pé a ò rí ìyàwó fún gbogbo wọn látojú ogun,+ ẹ̀yin náà ò sì lè fún wọn ní ìyàwó kí ẹ má jẹ̀bi.’”+
23 Torí náà, ohun tí àwọn ọkùnrin Bẹ́ńjámínì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì gbé lára àwọn obìnrin tó ń jó lọ láti fi ṣe aya. Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí ilẹ̀ tí wọ́n jogún, wọ́n tún àwọn ìlú wọn kọ́,+ wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.
24 Nígbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tú ká látibẹ̀, kálukú pa dà sọ́dọ̀ ẹ̀yà rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀, wọ́n sì kúrò níbẹ̀, kálukú pa dà sí ilẹ̀ tó jogún.
25 Kò sí ọba kankan ní Ísírẹ́lì+ nígbà yẹn. Kálukú ń ṣe ohun tó tọ́ lójú ara rẹ̀.*
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Tàbí “Mo ti fi.”
Ní Héb., “tí wọ́n fi kèké pín fún mi.”
Tàbí kó jẹ́, “ó pàtẹ́wọ́ látorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀.”
Tàbí “Négébù.”
Ó túmọ̀ sí “Bàsíà (Abọ́) Omi.”
Ó túmọ̀ sí “Ìparun Pátápátá.”
Ní Héb., “kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe.”
Ní Héb., “fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ọ.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Ní Héb., “ọwọ́.”
Ní Héb., “rinlẹ̀.”
Ó túmọ̀ sí “Àwọn Tó Ń Sunkún.”
Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.
Tàbí “jọ́sìn.”
Tàbí “bá àwọn ọlọ́run míì ṣèṣekúṣe.”
Tàbí “pèrò dà nípa wọn.”
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “Aramu-náháráímù.”
Ní Héb., “Árámù.”
Tàbí “Ilẹ̀ náà wá sinmi.”
Tàbí “owó òde.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kékeré tó jẹ́ nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 38 (ínǹṣì 15). Wo Àfikún B14.
Tàbí kó jẹ́, “ibi tí wọ́n ti ń wa òkúta.”
Tàbí “àga.”
Tàbí kó jẹ́, “ihò afẹ́fẹ́.”
Ní Héb., “ó ń bo ẹsẹ̀ rẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “ibi tí wọ́n ti ń wa òkúta.”
Tàbí “ilẹ̀ náà wá sinmi.”
Tàbí “Haroṣeti-há-góímù.”
Ní Héb., “ó.”
Ní Héb., “kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe.”
Tàbí “Pín àwọn ọkùnrin rẹ sórí.”
Tàbí “àfonífojì.”
Ní Héb., “kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe.”
Tàbí “àfonífojì.”
Tàbí “àwọn jagunjagun tó tú irun sílẹ̀ jọwọrọ.”
Tàbí “kọ orin sí.”
Tàbí kó jẹ́, “mì tìtì.”
Tàbí “Àwọn ará abúlé tán.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn tó ń gbé ohun èlò àwọn akọ̀wé.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ìyẹn, àpò ẹrù tí wọ́n máa ń so mọ́ ẹ̀yìn ẹranko arẹrù.
Tàbí “kórìíra ọkàn wọn.”
Tàbí “Odò.”
Tàbí “Odò.”
Tàbí “odò.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “wíńdò.”
Ní Héb., “Ilé ọmọ.”
Tàbí “Ilẹ̀ náà sì sinmi.”
Tàbí kó jẹ́, “ibi tí wọ́n ń kẹ́rù sí lábẹ́ ilẹ̀.”
Ní Héb., “fetí sí ohùn mi.”
Tàbí “wíìtì.”
Ní Héb., “Ẹgbẹ̀rún.”
Nǹkan bíi Lítà 22. Wo Àfikún B14.
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Jẹ́ Àlàáfíà.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ó túmọ̀ sí “Jẹ́ Kí Báálì Fi Òfin Gbèjà (Jà fún) Ara Rẹ̀.”
Tàbí “sọdá odò.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “gbé Gídíónì wọ̀.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “ọwọ́ rẹ máa lágbára.”
Láti nǹkan bí aago mẹ́wàá alẹ́ sí nǹkan bí aago méjì òru.
Ní Héb., “sọ ọ̀rọ̀ yìí.”
Ní Héb., “ẹ̀mí wọn rọlẹ̀, wọn ò sì ta kò ó mọ́.”
Ní Héb., “àtẹ́lẹwọ́ Séébà àti Sálímúnà.”
Ní Héb., “àtẹ́lẹwọ́ Séébà àti Sálímúnà.”
Tàbí “bí ọkùnrin bá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ ṣe máa tó.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “gbé orí wọn sókè.”
Tàbí “ilẹ̀ náà wá sinmi.”
Ní Héb., “ní àádọ́rin ọmọkùnrin tó jáde wá láti itan rẹ̀.”
Tàbí “Ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “agbo ilé bàbá ìyá rẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn onílẹ̀.”
Ní Héb., “egungun àti ẹran ara yín ni mí.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “ọwọ̀n.”
Tàbí “Ṣé kí n má so èso mọ́.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “fi ṣe olórí.”
Ní Héb., “rán ẹ̀mí burúkú sí àárín Ábímélékì àti àwọn olórí Ṣékémù.”
Tàbí “fi ọgbọ́n àrékérekè.”
Tàbí “ṣe ohun tí ọwọ́ rẹ bá ká sí i.”
Tàbí “ilé agbára.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “Síríà.”
Tàbí “ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀ mọ́ torí.”
Ní Héb., “ẹni tó ń gbọ́.”
Ní Héb., “Kí ló pa èmi àti ìwọ pọ̀?”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Ní Héb., “O ti rẹ̀ mí wálẹ̀ gan-an.”
Tàbí “kí n sì sunkún pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi torí mi ò ní lọ́kọ láé.”
Tàbí “ìlànà.”
Tàbí kó jẹ́, “wọ́n sọdá sí apá àríwá.”
Tàbí “mo fi ọkàn mi sọ́wọ́ mi.”
Ní Héb., “látinú ilé ọmọ.”
Ní Héb., “látinú ilé ọmọ.”
Ní Héb., “obìnrin kan lára àwọn ọmọbìnrin Filísínì.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Ní Héb., “òun ló tọ́ lójú mi.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí kó jẹ́, “kí oòrùn tó wọ yàrá inú.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “yàrá inú.”
Ní Héb., “pa wọ́n, ẹsẹ̀ lórí itan.”
Tàbí “pàlàpálá.”
Tàbí “de.”
Tàbí “pàlàpálá.”
Tàbí “dè.”
Ó túmọ̀ sí “Ibi Gíga Egungun Páárì Ẹ̀rẹ̀kẹ́.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “ẹ̀mí.”
Ó túmọ̀ sí “Ìsun Omi Ẹni Tó Ń Pè.”
Tàbí “Rọ̀ ọ́.”
Tàbí “fọ́nrán iṣan (ọṣán) tútù méje.”
Tàbí “èétú.”
Tàbí “mú mi ṣeré.”
Tàbí “ó rẹ ọkàn rẹ̀.”
Ní Héb., “látinú ilé ọlẹ̀ ìyá mi.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Ní Héb., “fi kún ọwọ́.”
Tàbí “ohun tó rò pé ó tọ́.”
Tàbí “agbani-nímọ̀ràn.”
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ ọmọ Léfì náà.”
Ní Héb., “ogún.”
Tàbí “ahọ́n.”
Ó túmọ̀ sí “Ibùdó Dánì.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “agbani-nímọ̀ràn.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “àwọn ọkùnrin tí ọkàn wọn gbọgbẹ́.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “kí o lè gbé ọkàn rẹ ró.”
Tàbí “kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ jẹ̀gbádùn.”
Tàbí “kí o lè gbé ọkàn rẹ ró.”
Ní Héb., “àgọ́.”
Tàbí “tí wọ́n dì ní gàárì.”
Tàbí kó jẹ́, “ilé Jèhófà ni mo sì ti ń sìn.”
Tàbí “oúnjẹ ẹran tí wọ́n pò mọ́ra.”
Tàbí “bá wọn lò pọ̀ kí ẹ sì ṣe ohun tó bá dáa lójú yín.”
Tàbí “Ẹ fi ọkàn yín sí i.”
Ní Héb., “bí ẹnì kan ṣoṣo.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn onílẹ̀.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “dìde bí ẹnì kan ṣoṣo.”
Ní Héb., “bí ẹnì kan ṣoṣo.”
Ní Héb., “dúró.”
Ní Héb., “pèéṣẹ́.”
Ní Héb., “àwọn ọmọbìnrin.”
Tàbí “ohun tó rò pé ó tọ́.”