ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Jòhánù 1:1-21:25
  • Jòhánù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jòhánù
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jòhánù

ÀKỌSÍLẸ̀ JÒHÁNÙ

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọ̀rọ̀ náà+ wà, Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run,+ Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan.*+ 2 Ẹni yìí wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní ìbẹ̀rẹ̀. 3 Ohun gbogbo wà nípasẹ̀ rẹ̀+ àti pé láìsí i, kò sí nǹkan kan tó wà.

Ohun tó wà 4 nípasẹ̀ rẹ̀ ni ìyè, ìyè náà sì ni ìmọ́lẹ̀ àwọn èèyàn.+ 5 Ìmọ́lẹ̀ náà ń tàn nínú òkùnkùn,+ àmọ́ òkùnkùn náà ò borí rẹ̀.

6 Ọkùnrin kan wà tí a rán láti jẹ́ aṣojú Ọlọ́run; Jòhánù+ ni orúkọ rẹ̀. 7 Ọkùnrin yìí wá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, kó lè jẹ́rìí nípa ìmọ́lẹ̀ náà,+ kí onírúurú èèyàn lè gbà gbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀. 8 Òun kọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yẹn,+ àmọ́ a ṣètò pé kó jẹ́rìí nípa ìmọ́lẹ̀ yẹn.

9 Ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tó ń fún onírúurú èèyàn ní ìmọ́lẹ̀ máa tó wá sí ayé.+ 10 Ó ti wà ní ayé,+ ayé sì wà nípasẹ̀ rẹ̀,+ àmọ́ ayé ò mọ̀ ọ́n. 11 Ó wá sí ilé òun fúnra rẹ̀, àmọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ ò gbà á. 12 Ṣùgbọ́n ó fún gbogbo àwọn tó gbà á ní àṣẹ láti di ọmọ Ọlọ́run,+ torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀.+ 13 A ò bí wọn látinú ẹ̀jẹ̀ tàbí látinú ìfẹ́ ti ara tàbí látinú ìfẹ́ èèyàn, àmọ́ a bí wọn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+

14 Torí náà, Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara,+ ó gbé láàárín wa, a sì rí ògo rẹ̀, irú ògo tó jẹ́ ti ọmọ bíbí kan ṣoṣo+ ti bàbá kan; ó sì kún fún oore Ọlọ́run* àti òtítọ́. 15 (Jòhánù jẹ́rìí nípa rẹ̀, àní, ó ké jáde pé: “Ẹni yìí ni mo sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi ti lọ níwájú mi, torí ó ti wà ṣáájú mi.’”)+ 16 Torí látinú ẹ̀kún rẹ̀, àní gbogbo wa gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí. 17 Torí a fúnni ní Òfin nípasẹ̀ Mósè,+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ àti òtítọ́ wà nípasẹ̀ Jésù Kristi.+ 18 Kò sí èèyàn tó rí Ọlọ́run rí;+ ọlọ́run bíbí kan ṣoṣo+ tó wà ní ẹ̀gbẹ́ Baba*+ ni ẹni tó ṣàlàyé Rẹ̀.+

19 Ẹ̀rí tí Jòhánù jẹ́ nìyí nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì láti Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lọ bi í pé: “Ta ni ọ́?”+ 20 Ó sọ òótọ́, kò sì sẹ́, ó ní: “Èmi kọ́ ni Kristi.” 21 Wọ́n bi í pé: “Ta wá ni ọ́? Ṣé ìwọ ni Èlíjà?”+ Ó dáhùn pé: “Èmi kọ́.” “Ṣé ìwọ ni Wòlíì náà?”+ Ó dáhùn pé: “Rárá!” 22 Wọ́n wá sọ fún un pé: “Ta ni ọ́? Sọ fún wa ká lè mọ ohun tí a máa sọ fún àwọn tó rán wa níṣẹ́. Kí lo sọ nípa ara rẹ?” 23 Ó sọ pé: “Èmi ni ohùn ẹni tó ń ké nínú aginjù pé, ‘Ẹ mú ọ̀nà Jèhófà* tọ́,’+ bí wòlíì Àìsáyà ṣe sọ.”+ 24 Àwọn Farisí ló rán àwọn èèyàn yìí. 25 Torí náà, wọ́n bi í pé: “Kí ló dé tí o fi ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn èèyàn tí kì í bá ṣe ìwọ ni Kristi tàbí Èlíjà tàbí Wòlíì náà?” 26 Jòhánù dá wọn lóhùn pé: “Omi ni mo fi ń batisí. Ẹnì kan wà láàárín yín tí ẹ kò mọ̀, 27 ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí mi ò tó tú okùn bàtà rẹ̀.”+ 28 Àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ ní Bẹ́tánì ní òdìkejì Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn.+

29 Lọ́jọ́ kejì, ó rí i tí Jésù ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó wá sọ pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ Ọlọ́run tó kó ẹ̀ṣẹ̀+ ayé lọ!+ 30 Ẹni yìí ni mo sọ nípa rẹ̀ pé: ‘Ọkùnrin kan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ó ti lọ níwájú mi, torí ó wà ṣáájú mi.’+ 31 Èmi gan-an ò mọ̀ ọ́n, àmọ́ ìdí tí mo fi wá, tí mò ń fi omi batisí ni pé ká lè fi í hàn kedere fún Ísírẹ́lì.”+ 32 Jòhánù náà jẹ́rìí sí i, ó ní: “Mo rí i tí ẹ̀mí ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà láti ọ̀run, ó sì bà lé e.+ 33 Èmi gan-an ò mọ̀ ọ́n, àmọ́ Ẹni tó rán mi láti fi omi batisí sọ fún mi pé: ‘Ẹnikẹ́ni tí o bá rí tí ẹ̀mí ń sọ̀ kalẹ̀, tó sì bà lé,+ òun ni ẹni tó ń fi ẹ̀mí mímọ́ batisí.’+ 34 Mo ti rí i, mo sì ti jẹ́rìí pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.”+

35 Nígbà tó tún di ọjọ́ kejì, Jòhánù dúró pẹ̀lú méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, 36 bó sì ṣe rí Jésù tó ń rìn lọ, ó sọ pé: “Ẹ wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ Ọlọ́run!” 37 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjèèjì gbọ́ ohun tó sọ yìí, wọ́n tẹ̀ lé Jésù. 38 Jésù wá yíjú pa dà, bó sì ṣe rí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé òun, ó bi wọ́n pé: “Kí lẹ̀ ń wá?” Wọ́n sọ fún un pé: “Rábì (tó túmọ̀ sí “Olùkọ́”), ibo lò ń gbé?” 39 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, kí ẹ wá wò ó.” Wọ́n wá lọ wo ibi tó ń gbé, wọ́n sì dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ yẹn; nǹkan bíi wákàtí kẹwàá ni.* 40 Áńdérù+ arákùnrin Símónì Pétérù wà lára àwọn méjì tó gbọ́ ohun tí Jòhánù sọ, tí wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù. 41 Ó kọ́kọ́ wá Símónì arákùnrin rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “A ti rí Mèsáyà náà”+ (tó túmọ̀ sí “Kristi”), 42 ó sì mú un lọ sọ́dọ̀ Jésù. Nígbà tí Jésù wò ó, ó sọ pé: “Ìwọ ni Símónì,+ ọmọ Jòhánù; a ó máa pè ọ́ ní Kéfà” (tó túmọ̀ sí “Pétérù”).+

43 Lọ́jọ́ kejì, ó fẹ́ lọ sí Gálílì. Jésù wá rí Fílípì,+ ó sì sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.” 44 Bẹtisáídà, ìlú Áńdérù àti Pétérù, ni Fílípì ti wá. 45 Fílípì rí Nàtáníẹ́lì,+ ó sì sọ fún un pé: “A ti rí ẹni tí Mósè, nínú Òfin àti àwọn Wòlíì kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: Jésù, ọmọ Jósẹ́fù,+ láti Násárẹ́tì.” 46 Àmọ́ Nàtáníẹ́lì sọ fún un pé: “Ṣé ohun rere kankan lè wá láti Násárẹ́tì?” Fílípì sọ fún un pé: “Wá wò ó.” 47 Jésù rí i tí Nàtáníẹ́lì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì sọ nípa rẹ̀ pé: “Wò ó, ní tòótọ́, ọmọ Ísírẹ́lì tí ẹ̀tàn kankan ò sí nínú rẹ̀.”+ 48 Nàtáníẹ́lì bi í pé: “Báwo lo ṣe mọ̀ mí?” Jésù dá a lóhùn pé: “Kí Fílípì tó pè ọ́, nígbà tí o wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, ni mo ti rí ọ.” 49 Nàtáníẹ́lì dá a lóhùn pé: “Rábì, ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run, ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”+ 50 Jésù sọ fún un pé: “Ṣé torí pé mo sọ fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ lo ṣe gbà gbọ́? O máa rí àwọn nǹkan tó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ.” 51 Ó wá sọ fún un pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹ máa rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, tí àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń gòkè, tí wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ sọ́dọ̀ Ọmọ èèyàn.”+

2 Ní ọjọ́ kẹta, àsè ìgbéyàwó kan wáyé ní Kánà ti Gálílì, ìyá Jésù sì wà níbẹ̀. 2 Wọ́n pe Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà síbi àsè ìgbéyàwó náà.

3 Nígbà tí wáìnì ò tó mọ́, ìyá Jésù sọ fún un pé: “Wọn ò ní wáìnì kankan.” 4 Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún un pé: “Obìnrin yìí, báwo ni ìyẹn ṣe kan èmi àti ìwọ?* Wákàtí mi ò tíì tó.” 5 Ìyá rẹ̀ sọ fún àwọn tó ń pín jíjẹ mímu pé: “Ẹ ṣe ohunkóhun tó bá ní kí ẹ ṣe.” 6 Ìṣà omi mẹ́fà tí wọ́n fi òkúta ṣe wà níbẹ̀, bí òfin ìwẹ̀mọ́ àwọn Júù+ ṣe sọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan lè gba òṣùwọ̀n méjì tàbí mẹ́ta tó jẹ́ ti nǹkan olómi.* 7 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ pọn omi kún inú àwọn ìṣà náà.” Torí náà, wọ́n pọn omi kún un dé ẹnu. 8 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ó yá, ẹ bu díẹ̀, kí ẹ sì gbé e lọ fún alága àsè.” Ni wọ́n bá gbé e lọ. 9 Nígbà tí alága àsè tọ́ omi tí Jésù sọ di wáìnì wò, láìmọ ibi tó ti wá (bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ tó bu omi náà mọ̀), alága àsè pe ọkọ ìyàwó, 10 ó sì sọ fún un pé: “Wáìnì tó dáa ni gbogbo èèyàn máa ń kọ́kọ́ gbé jáde, tí àwọn èèyàn bá sì ti yó, wọ́n á gbé gbàrọgùdù jáde. Wáìnì tó dáa lo gbé pa mọ́ títí di àkókò yìí.” 11 Jésù ṣe èyí ní Kánà ti Gálílì láti fi bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀, ó sì mú kí ògo rẹ̀ hàn kedere,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.

12 Lẹ́yìn náà, òun, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀+ àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí Kápánáúmù,+ àmọ́ wọn ò pẹ́ níbẹ̀.

13 Ìrékọjá+ àwọn Júù ti sún mọ́lé, Jésù sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. 14 Ó rí àwọn tó ń ta màlúù, àgùntàn àti àdàbà+ nínú tẹ́ńpìlì, ó sì rí àwọn tó ń pààrọ̀ owó lórí ìjókòó wọn. 15 Torí náà, ó fi okùn ṣe ẹgba, ó sì lé gbogbo àwọn tó ní àgùntàn àti màlúù jáde nínú tẹ́ńpìlì, ó da ẹyọ owó àwọn tó ń pààrọ̀ owó sílẹ̀, ó sì dojú àwọn tábìlì wọn dé.+ 16 Ó sọ fún àwọn tó ń ta àdàbà pé: “Ẹ kó àwọn nǹkan yìí kúrò níbí! Ẹ yéé sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!”*+ 17 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé a ti kọ ọ́ pé: “Ìtara ilé rẹ máa gbà mí lọ́kàn.”+

18 Torí náà, àwọn Júù sọ fún un pé: “Àmì wo lo máa fi hàn wá,+ torí o ti ń ṣe àwọn nǹkan yìí?” 19 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ wó tẹ́ńpìlì yìí lulẹ̀, màá sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ.”+ 20 Àwọn Júù wá sọ pé: “Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta (46) ni wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì yìí, ṣé ọjọ́ mẹ́ta lo máa wá fi kọ́ ọ?” 21 Àmọ́ tẹ́ńpìlì ti ara rẹ̀ ló ń sọ.+ 22 Nígbà tí a wá jí i dìde, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé ó máa ń sọ bẹ́ẹ̀,+ wọ́n sì gba ìwé mímọ́ àti ohun tí Jésù sọ gbọ́.

23 Nígbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà àjọyọ̀ Ìrékọjá, ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n rí àwọn iṣẹ́ àmì tó ń ṣe. 24 Àmọ́ Jésù ò gbára lé wọn, torí pé ó mọ gbogbo wọn, 25 kò sì nílò kí ẹnikẹ́ni jẹ́rìí nípa èèyàn, torí ó mọ ohun tó wà nínú èèyàn.+

3 Ọkùnrin kan wà tó jẹ́ Farisí, Nikodémù+ ni orúkọ rẹ̀, alákòóso àwọn Júù ni. 2 Ẹni yìí wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní òru,+ ó sì sọ fún un pé: “Rábì,+ a mọ̀ pé olùkọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọ́, torí kò sẹ́ni tó lè ṣe àwọn iṣẹ́ àmì+ tí ò ń ṣe yìí, àfi tí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú rẹ̀.”+ 3 Jésù dá a lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, tí a kò bá tún ẹnikẹ́ni bí,*+ kò lè rí Ìjọba Ọlọ́run.”+ 4 Nikodémù sọ fún un pé: “Báwo ni wọ́n ṣe lè bí èèyàn nígbà tó ti dàgbà? Kò lè wọnú ikùn ìyá rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, kí ìyá rẹ̀ sì bí i, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?” 5 Jésù dáhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, tí a kò bá bí ẹnì kan látinú omi+ àti ẹ̀mí,+ kò lè wọ Ìjọba Ọlọ́run. 6 Ẹran ara ni ohun tí a bí látinú ẹran ara, ẹ̀mí sì ni ohun tí a bí látinú ẹ̀mí. 7 Má ṣe jẹ́ kí ẹnu yà ọ́ torí mo sọ fún ọ pé: A gbọ́dọ̀ tún yín bí. 8 Ibi tó bá wu atẹ́gùn ló máa ń fẹ́ sí, o sì máa ń gbọ́ ìró rẹ̀, àmọ́ o ò mọ ibi tó ti wá àti ibi tó ń lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún gbogbo ẹni tí a bí látinú ẹ̀mí.”+

9 Nikodémù fèsì pé: “Báwo ni àwọn nǹkan yìí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?” 10 Jésù dá a lóhùn pé: “Ṣebí olùkọ́ ni ọ́ ní Ísírẹ́lì, kí ló dé tí o ò mọ àwọn nǹkan yìí? 11 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, ohun tí a mọ̀ là ń sọ, ohun tí a sì rí là ń jẹ́rìí sí, àmọ́ ẹ̀yin ò gba ẹ̀rí tí a jẹ́. 12 Tí mo bá sọ àwọn nǹkan ti ayé fún yín, síbẹ̀ tí ẹ ò gbà gbọ́, báwo lẹ ṣe máa gbà gbọ́ tí mo bá sọ àwọn nǹkan ti ọ̀run fún yín? 13 Bákan náà, kò sí èèyàn kankan tó tíì gòkè lọ sọ́run+ àfi ẹni tó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run,+ ìyẹn Ọmọ èèyàn. 14 Àti pé bí Mósè ṣe gbé ejò sókè ní aginjù,+ bẹ́ẹ̀ náà la gbọ́dọ̀ gbé Ọmọ èèyàn sókè,+ 15 kí gbogbo ẹni tó bá gbà á gbọ́ lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.+

16 “Torí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni,+ kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.+ 17 Torí Ọlọ́run ò rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé kó lè ṣèdájọ́ ayé, àmọ́ ó rán an kí ayé lè rí ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀.+ 18 A ò ní dá ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lẹ́jọ́.+ Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní ìgbàgbọ́, a ti dá a lẹ́jọ́ ná, torí pé kò ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run.+ 19 Ohun tí a máa gbé ìdájọ́ kà nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ti wá sí ayé,+ àmọ́ àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, torí pé oníṣẹ́ ibi ni wọ́n. 20 Torí ẹnikẹ́ni tó bá ń hùwà burúkú kórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sínú ìmọ́lẹ̀, kí a má bàa dá àwọn iṣẹ́ rẹ̀ lẹ́bi.* 21 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe ohun tó tọ́ máa ń wá sínú ìmọ́lẹ̀,+ ká lè fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn kedere pé ó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.”

22 Lẹ́yìn èyí, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ìgbèríko Jùdíà, ó lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi.+ 23 Àmọ́ Jòhánù náà ń ṣèrìbọmi ní Áínónì nítòsí Sálímù, torí pé omi púpọ̀ wà níbẹ̀,+ àwọn èèyàn ń wá ṣáá, ó sì ń ṣèrìbọmi fún wọn;+ 24 wọn ò tíì fi Jòhánù sẹ́wọ̀n+ nígbà yẹn.

25 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù ń bá Júù kan fa ọ̀rọ̀ ìwẹ̀mọ́. 26 Torí náà, wọ́n wá sọ́dọ̀ Jòhánù, wọ́n sì sọ fún un pé: “Rábì, ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ rẹ ní òdìkejì Jọ́dánì, ẹni tí o jẹ́rìí nípa rẹ̀,+ wò ó, ẹni yìí ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn, gbogbo èèyàn sì ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” 27 Jòhánù dá wọn lóhùn pé: “Èèyàn ò lè rí nǹkan kan gbà àfi tí a bá fún un láti ọ̀run. 28 Ẹ̀yin fúnra yín jẹ́rìí sí i pé mo sọ pé, ‘Èmi kọ́ ni Kristi,+ àmọ́ a ti rán mi jáde ṣáájú ẹni yẹn.’+ 29 Ẹnikẹ́ni tó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó.+ Àmọ́ tí ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó bá dúró, tó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, inú rẹ̀ máa dùn gan-an torí ohùn ọkọ ìyàwó. Torí náà, ayọ̀ mi ti kún rẹ́rẹ́. 30 Ẹni yẹn gbọ́dọ̀ máa pọ̀ sí i, àmọ́ èmi gbọ́dọ̀ máa dín kù.”

31 Ẹni tó wá láti òkè+ ga ju gbogbo àwọn yòókù lọ. Ẹni tó wá láti ayé, ará ayé ni, àwọn nǹkan ti ayé ló sì ń sọ. Ẹni tó wá láti ọ̀run ga ju gbogbo àwọn yòókù lọ.+ 32 Ó ń jẹ́rìí sí ohun tó ti rí, tó sì ti gbọ́,+ àmọ́ èèyàn kankan ò gba ẹ̀rí rẹ̀.+ 33 Ẹnikẹ́ni tó bá gba ẹ̀rí rẹ̀ ti gbé èdìdì rẹ̀ lé e pé* olóòótọ́ ni Ọlọ́run.+ 34 Torí ẹni tí Ọlọ́run rán ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+ torí pé Òun kì í fúnni ní ẹ̀mí tí kò pọ̀ tó.* 35 Baba nífẹ̀ẹ́ Ọmọ,+ ó sì ti fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.+ 36 Ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun;+ ẹni tó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kò ní rí ìyè,+ àmọ́ ìbínú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.+

4 Nígbà tí Olúwa mọ̀ pé àwọn Farisí ti gbọ́ pé àwọn tí Jésù ń sọ di ọmọ ẹ̀yìn, tó sì ń ṣèrìbọmi+ fún pọ̀ ju ti Jòhánù lọ— 2 bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù fúnra rẹ̀ kọ́ ló ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni— 3 ó kúrò ní Jùdíà, ó sì tún lọ sí Gálílì. 4 Àmọ́ ó pọn dandan pé kó gba Samáríà kọjá. 5 Ó wá dé ìlú kan ní Samáríà tí wọ́n ń pè ní Síkárì, nítòsí pápá tí Jékọ́bù fún Jósẹ́fù ọmọ rẹ̀.+ 6 Kódà, kànga Jékọ́bù wà níbẹ̀.+ Àmọ́ ìrìn àjò náà ti mú kó rẹ Jésù, torí náà, ó jókòó síbi kànga* náà. Ó jẹ́ nǹkan bíi wákàtí kẹfà.*

7 Obìnrin ará Samáríà kan wá fa omi. Jésù sọ fún un pé: “Fún mi lómi mu.” 8 (Torí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sínú ìlú láti ra oúnjẹ.) 9 Obìnrin ará Samáríà náà wá sọ fún un pé: “Báwo ni ìwọ, tí o jẹ́ Júù, ṣe máa ní kí èmi, obìnrin ará Samáríà fún ọ lómi?” (Torí àwọn Júù kì í ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ará Samáríà.)+ 10 Jésù dá a lóhùn pé: “Ká ní o mọ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run+ ni, tí o sì mọ ẹni tó sọ fún ọ pé, ‘Fún mi lómi mu,’ ṣe lò bá bi í, ì bá sì ti fún ọ ní omi ìyè.”+ 11 Obìnrin náà sọ fún un pé: “Ọ̀gá, o ò tiẹ̀ ní korobá tí o máa fi fa omi, kànga náà sì jìn. Ibo lo ti wá fẹ́ rí omi ìyè yìí? 12 O ò tóbi ju Jékọ́bù baba ńlá wa lọ, ẹni tó fún wa ní kànga náà, tí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹran rẹ̀ mu nínú rẹ̀, àbí o tóbi jù ú lọ?” 13 Jésù dá a lóhùn pé: “Gbogbo ẹni tó bá ń mu látinú omi yìí, òùngbẹ tún máa gbẹ ẹ́. 14 Ẹnikẹ́ni tó bá mu látinú omi tí màá fún un, òùngbẹ ò ní gbẹ ẹ́ láé,+ àmọ́ omi tí màá fún un á di ìsun omi nínú rẹ̀, á sì máa tú yàà jáde láti fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun.”+ 15 Obìnrin náà sọ fún un pé: “Ọ̀gá, fún mi ní omi yìí, kí òùngbẹ má bàa gbẹ mí, kí n má sì máa wá síbí yìí láti fa omi.”

16 Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ẹ sì wá síbí yìí.” 17 Obìnrin náà fèsì pé: “Mi ò ní ọkọ.” Jésù sọ fún un pé: “Òótọ́ lo sọ, bí o ṣe sọ pé, ‘Mi ò ní ọkọ.’ 18 Torí o ti ní ọkọ márùn-ún rí, ọkùnrin tí o sì ń fẹ́ báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Òótọ́ lohun tí o sọ yìí.” 19 Obìnrin náà sọ fún un pé: “Ọ̀gá, mo rí i pé wòlíì ni ọ́.+ 20 Orí òkè yìí ni àwọn baba ńlá wa ti jọ́sìn, àmọ́ ẹ̀yin sọ pé Jerúsálẹ́mù ni àwọn èèyàn ti gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn.”+ 21 Jésù sọ fún un pé: “Gbà mí gbọ́, obìnrin yìí, wákàtí náà ń bọ̀ tí ẹ ò ní máa jọ́sìn Baba lórí òkè yìí tàbí ní Jerúsálẹ́mù. 22 Ẹ̀ ń jọ́sìn ohun tí ẹ ò mọ̀;+ àwa ń jọ́sìn ohun tí a mọ̀, torí ọ̀dọ̀ àwọn Júù ni ìgbàlà ti bẹ̀rẹ̀.+ 23 Síbẹ̀, wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn olùjọsìn tòótọ́ á máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, torí ní tòótọ́, irú àwọn ẹni yìí ni Baba ń wá pé kí wọ́n máa jọ́sìn òun.+ 24 Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí,+ àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”+ 25 Obìnrin náà sọ fún un pé: “Mo mọ̀ pé Mèsáyà ń bọ̀, ẹni tí wọ́n ń pè ní Kristi. Nígbàkigbà tí ẹni yẹn bá dé, ó máa sọ gbogbo nǹkan fún wa ní gbangba.” 26 Jésù sọ fún un pé: “Èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni ẹni náà.”+

27 Ìgbà yẹn ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ó sì yà wọ́n lẹ́nu pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀. Lóòótọ́, kò sẹ́ni tó sọ pé: “Kí lò ń wá?” tàbí “Kí ló dé tó ò ń bá obìnrin náà sọ̀rọ̀?” 28 Torí náà, obìnrin náà fi ìṣà omi rẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sínú ìlú, ó sì sọ fún àwọn èèyàn pé: 29 “Ẹ wá wo ọkùnrin kan tó sọ gbogbo ohun tí mo ṣe fún mi. Ṣé kì í ṣe pé òun ni Kristi?” 30 Wọ́n wá kúrò nínú ìlú, wọ́n sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.

31 Ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń rọ̀ ọ́, pé: “Rábì,+ jẹun.” 32 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Mo ní oúnjẹ tí màá jẹ tí ẹ ò mọ̀ nípa rẹ̀.” 33 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ láàárín ara wọn pé: “Ẹnì kankan ò gbé oúnjẹ wá fún un, àbí?” 34 Jésù sọ fún wọn pé: “Oúnjẹ mi ni pé kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi,+ kí n sì parí iṣẹ́ rẹ̀.+ 35 Ṣebí ẹ sọ pé ó ṣì ku oṣù mẹ́rin kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀? Ẹ wò ó! Mò ń sọ fún yín pé: Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun, wọ́n ti tó kórè.+ Ní báyìí, 36 olùkórè ti ń gba èrè, ó sì ń kó èso jọ fún ìyè àìnípẹ̀kun, kí afúnrúgbìn àti olùkórè lè jọ yọ̀.+ 37 Lórí ọ̀rọ̀ yìí, òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà pé: Ẹnì kan ni afúnrúgbìn, ẹlòmíì sì ni olùkórè. 38 Mo rán yín pé kí ẹ lọ kórè ohun tí ẹ ò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíì ti ṣiṣẹ́, ẹ sì ti wọlé láti jàǹfààní iṣẹ́ wọn.”

39 Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà láti ìlú yẹn gbà á gbọ́ torí ọ̀rọ̀ obìnrin tó jẹ́rìí sí i pé: “Gbogbo ohun tí mo ṣe ló sọ fún mi.”+ 40 Torí náà, nígbà tí àwọn ará Samáríà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ní kó dúró sọ́dọ̀ àwọn, ó sì dúró síbẹ̀ fún ọjọ́ méjì. 41 Torí èyí, àwọn tó gbà á gbọ́ pọ̀ sí i torí ohun tó sọ, 42 wọ́n sì sọ fún obìnrin náà pé: “Kì í ṣe ohun tí o sọ nìkan ló mú ká gbà gbọ́; torí àwa fúnra wa ti gbọ́, a sì mọ̀ pé olùgbàlà ayé ni ọkùnrin yìí lóòótọ́.”+

43 Lẹ́yìn ọjọ́ méjì náà, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Gálílì. 44 Jésù fúnra rẹ̀ jẹ́rìí sí i pé wòlíì kì í gbayì ní ìlú rẹ̀.+ 45 Torí náà, nígbà tó dé Gálílì, àwọn ará Gálílì tẹ́wọ́ gbà á, torí pé wọ́n ti rí gbogbo ohun tó ṣe ní Jerúsálẹ́mù nígbà àjọyọ̀,+ torí àwọn náà lọ síbi àjọyọ̀ náà.+

46 Ó tún wá sí Kánà ti Gálílì, níbi tó ti sọ omi di wáìnì.+ Òṣìṣẹ́ ọba kan wà tí ọmọkùnrin rẹ̀ ń ṣàìsàn ní Kápánáúmù. 47 Nígbà tí ọkùnrin yìí gbọ́ pé Jésù ti kúrò ní Jùdíà wá sí Gálílì, ó lọ bá a, ó sì ní kó máa bọ̀ wá wo ọmọ òun sàn, torí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. 48 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Láìjẹ́ pé ẹ̀yin rí àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ ò ní gbà gbọ́ láé.”+ 49 Òṣìṣẹ́ ọba náà sọ fún un pé: “Olúwa, sọ̀ kalẹ̀ wá kí ọmọ mi kékeré tó kú.” 50 Jésù sọ fún un pé: “Máa lọ; ọmọ rẹ ti yè.”+ Ọkùnrin náà gba ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún un gbọ́, ó sì lọ. 51 Àmọ́ bó ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ lọ, àwọn ẹrú rẹ̀ pàdé rẹ̀ kí wọ́n lè sọ fún un pé ọmọ rẹ̀ ti yè.* 52 Ó wá bi wọ́n nípa wákàtí tí ara rẹ̀ yá. Wọ́n dá a lóhùn pé: “Wákàtí keje* ni ibà náà fi í sílẹ̀ lánàá.” 53 Bàbá náà wá mọ̀ pé wákàtí yẹn gangan ni Jésù sọ fún òun pé: “Ọmọ rẹ ti yè.”+ Torí náà, òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ gbà á gbọ́. 54 Iṣẹ́ àmì kejì+ tí Jésù ṣe nìyí nígbà tó kúrò ní Jùdíà wá sí Gálílì.

5 Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, àjọyọ̀ kan + tí àwọn Júù máa ń ṣe wáyé, Jésù sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. 2 Adágún omi kan wà ní Jerúsálẹ́mù níbi Ibodè Àgùntàn+ tí wọ́n ń pè ní Bẹtisátà lédè Hébérù, ó ní ọ̀dẹ̀dẹ̀* márùn-ún. 3 Inú ibẹ̀ ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn aláìsàn, afọ́jú, arọ àti àwọn tó rọ lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀ dùbúlẹ̀ sí. 4* —— 5 Àmọ́ ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó ti ń ṣàìsàn fún ọdún méjìdínlógójì (38). 6 Jésù rí ọkùnrin yìí tó dùbúlẹ̀ síbẹ̀, ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tó ti ń ṣàìsàn, ó wá sọ fún ọkùnrin náà pé: “Ṣé o fẹ́ kí ara rẹ yá?”+ 7 Ọkùnrin aláìsàn náà dá a lóhùn pé: “Ọ̀gá, mi ò lẹ́ni tó lè gbé mi sínú adágún omi náà tó bá ti rú, torí tí n bá ti ń lọ síbẹ̀, ẹlòmíì á ti sọ̀ kalẹ̀ ṣáájú mi.” 8 Jésù sọ fún un pé: “Dìde! Gbé ẹní* rẹ, kí o sì máa rìn.”+ 9 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ara ọkùnrin náà yá, ó gbé ẹní* rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn.

Ọjọ́ Sábáàtì ni. 10 Torí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọkùnrin tó wò sàn náà pé: “Sábáàtì nìyí, kò sì bófin mu fún ọ láti gbé ẹní* náà.”+ 11 Àmọ́ ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹni tó wò mí sàn náà ló sọ fún mi pé, ‘Gbé ẹní* rẹ, kí o sì máa rìn.’” 12 Wọ́n bi í pé: “Ta lẹni tó sọ fún ọ pé, ‘Gbé e, kí o sì máa rìn’?” 13 Àmọ́ ọkùnrin tí ara rẹ̀ ti yá náà ò mọ ẹni náà, torí Jésù ti wọ àárín àwọn èrò tó wà níbẹ̀.

14 Lẹ́yìn náà, Jésù rí i nínú tẹ́ńpìlì, ó sì sọ fún un pé: “Wò ó, ara rẹ ti yá. Má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí nǹkan tó burú ju ti tẹ́lẹ̀ má bàa ṣẹlẹ̀ sí ọ.” 15 Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé Jésù ló wo òun sàn. 16 Torí èyí, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí Jésù, torí pé ó ń ṣe àwọn nǹkan yìí lọ́jọ́ Sábáàtì. 17 Àmọ́, ó dá wọn lóhùn pé: “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di báyìí, èmi náà ṣì ń ṣiṣẹ́.”+ 18 Ìdí nìyí tí àwọn Júù fi túbọ̀ ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á, torí kì í ṣe pé kò pa Sábáàtì mọ́ nìkan ni, àmọ́ ó tún ń pe Ọlọ́run ní Baba rẹ̀,+ ó ń sọ pé òun àti Ọlọ́run dọ́gba.+

19 Torí náà, Jésù dá wọn lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, Ọmọ ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara rẹ̀, àfi ohun tó bá rí tí Baba ń ṣe nìkan.+ Torí ohunkóhun tí Ẹni yẹn bá ṣe, àwọn nǹkan yìí ni Ọmọ náà ń ṣe lọ́nà kan náà. 20 Torí Baba ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọmọ,+ ó sì ń fi gbogbo ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe hàn án, ó sì máa fi àwọn iṣẹ́ tó tóbi ju èyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín.+ 21 Torí bí Baba ṣe ń jí àwọn òkú dìde gẹ́lẹ́, tó sì ń mú kí wọ́n wà láàyè,+ bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ ń sọ àwọn tí òun bá fẹ́ di alààyè.+ 22 Torí Baba kì í ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni, àmọ́ ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé Ọmọ lọ́wọ́,+ 23 kí gbogbo ẹ̀dá lè máa bọlá fún Ọmọ bí wọ́n ṣe ń bọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá bọlá fún Ọmọ, kò bọlá fún Baba tó rán an.+ 24 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tó sì gba Ẹni tó rán mi gbọ́, ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ a ò sì ní dá a lẹ́jọ́, àmọ́ ó ti tinú ikú bọ́ sínú ìyè.+

25 “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn òkú máa gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọ́run, tí àwọn tó fiyè sílẹ̀ sì máa yè. 26 Torí bí Baba ṣe ní ìyè nínú ara rẹ̀,*+ bẹ́ẹ̀ náà ló yọ̀ǹda fún Ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀.+ 27 Ó sì ti fún un ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́,+ torí òun ni Ọmọ èèyàn.+ 28 Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu, torí wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀,+ 29 tí wọ́n á sì jáde wá, àwọn tó ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.+ 30 Mi ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara mi. Ohun tí mò ń gbọ́ ni mo fi ń ṣèdájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi,+ torí kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mò ń wá, ìfẹ́ ẹni tó rán mi ni.+

31 “Tí èmi nìkan bá jẹ́rìí nípa ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òótọ́.+ 32 Ẹlòmíì wà tó ń jẹ́rìí nípa mi, mo sì mọ̀ pé òótọ́ ni ẹ̀rí tó ń jẹ́ nípa mi.+ 33 Ẹ ti rán àwọn èèyàn sí Jòhánù, ó sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́.+ 34 Àmọ́ mi ò gba ẹ̀rí látọ̀dọ̀ èèyàn, ṣùgbọ́n mo sọ àwọn nǹkan yìí kí ẹ lè rígbàlà. 35 Fìtílà tó ń jó, tó sì ń tàn yòò ni ọkùnrin yẹn, ó sì wù yín pé kí ẹ yọ̀ gidigidi nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ fúngbà díẹ̀.+ 36 Àmọ́ mo ní ẹ̀rí tó tóbi ju ti Jòhánù lọ, torí àwọn iṣẹ́ tí Baba mi yàn fún mi pé kí n ṣe, àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe yìí, ń jẹ́rìí sí i pé Baba ló rán mi.+ 37 Baba tó sì rán mi ti fúnra rẹ̀ jẹ́rìí nípa mi.+ Ẹ ò tíì gbọ́ ohùn rẹ̀ rí, ẹ ò sì fojú rí bó ṣe rí,+ 38 ẹ ò sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé inú yín, torí pé ẹ ò gba ẹni tó rán gbọ́.

39 “Ẹ̀ ń wá inú Ìwé Mímọ́,+ torí ẹ rò pé ó máa jẹ́ kí ẹ ní ìyè àìnípẹ̀kun; àwọn yìí* gan-an ló sì ń jẹ́rìí nípa mi.+ 40 Síbẹ̀, ẹ ò fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi+ kí ẹ lè ní ìyè. 41 Èmi kì í gba ògo látọ̀dọ̀ èèyàn, 42 àmọ́ mo mọ̀ dáadáa pé ẹ ò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín. 43 Mo wá ní orúkọ Baba mi, àmọ́ ẹ ò gbà mí. Tí ẹlòmíì bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ máa gba ẹni yẹn. 44 Báwo lẹ ṣe máa gbà gbọ́, nígbà tó jẹ́ pé ẹ̀ ń gba ògo látọ̀dọ̀ ara yín, ẹ ò sì wá ògo tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run+ kan ṣoṣo náà? 45 Ẹ má rò pé màá fẹ̀sùn kàn yín lọ́dọ̀ Baba; ẹnì kan wà tó ń fẹ̀sùn kàn yín, Mósè ni,+ ẹni tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé. 46 Àní, tí ẹ bá gba Mósè gbọ́, ẹ máa gbà mí gbọ́, torí ó kọ̀wé nípa mi.+ 47 Àmọ́ tí ẹ ò bá gba ohun tó kọ gbọ́, báwo lẹ ṣe máa gba ohun tí mo sọ gbọ́?”

6 Lẹ́yìn náà, Jésù gbéra lọ sí òdìkejì Òkun Gálílì tàbí Tìbéríà.+ 2 Èrò rẹpẹtẹ ń tẹ̀ lé e ṣáá,+ torí wọ́n ń kíyè sí àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ń ṣe, bó ṣe ń wo àwọn aláìsàn sàn.+ 3 Torí náà, Jésù lọ sórí òkè kan, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì jókòó síbẹ̀. 4 Ìrékọjá,+ tó jẹ́ àjọyọ̀ àwọn Júù, ti sún mọ́lé. 5 Nígbà tí Jésù gbójú sókè, tó sì rí i pé èrò rẹpẹtẹ ń bọ̀ lọ́dọ̀ òun, ó sọ fún Fílípì pé: “Ibo la ti máa ra búrẹ́dì táwọn èèyàn yìí máa jẹ?”+ 6 Àmọ́ ó ń sọ èyí kó lè dán an wò, torí ó mọ ohun tí òun máa tó ṣe. 7 Fílípì dá a lóhùn pé: “Búrẹ́dì igba (200) owó dínárì* ò lè tó wọn, ká tiẹ̀ ní díẹ̀ ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa jẹ.” 8 Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, Áńdérù arákùnrin Símónì Pétérù, sọ fún un pé: 9 “Ọmọdékùnrin kan nìyí tó ní búrẹ́dì ọkà báálì márùn-ún àti ẹja kéékèèké méjì. Àmọ́ kí ni èyí já mọ́ láàárín àwọn tó pọ̀ tó yìí?”+

10 Jésù sọ pé: “Ẹ ní kí àwọn èèyàn náà jókòó.” Torí pé koríko pọ̀ gan-an níbẹ̀, àwọn èèyàn náà jókòó, wọ́n jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000).+ 11 Jésù mú búrẹ́dì náà, lẹ́yìn tó dúpẹ́, ó pín in fún àwọn tó jókòó síbẹ̀; ó ṣe ohun kan náà sí àwọn ẹja kéékèèké náà, wọ́n sì rí oúnjẹ tó pọ̀ tó bí wọ́n ṣe fẹ́. 12 Àmọ́ nígbà tí wọ́n yó, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kó àwọn ohun tó ṣẹ́ kù jọ, kí ohunkóhun má bàa ṣòfò.” 13 Torí náà, lẹ́yìn tí àwọn tó jẹ látinú búrẹ́dì ọkà báálì márùn-ún náà jẹun tán, wọ́n kó ohun tó ṣẹ́ kù jọ, ó sì kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).

14 Nígbà tí àwọn èèyàn rí iṣẹ́ àmì tó ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ó dájú pé Wòlíì tí wọ́n ní ó máa wá sí ayé nìyí.”+ 15 Jésù mọ̀ pé wọ́n máa tó wá mú òun láti fi òun jẹ ọba, torí náà, ó tún kúrò níbẹ̀,+ ó sì lọ sórí òkè lóun nìkan.+

16 Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí òkun,+ 17 wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì forí lé Kápánáúmù. Ilẹ̀ ti wá ṣú báyìí, Jésù ò sì tíì wá bá wọn.+ 18 Bákan náà, òkun ti ń ru gùdù torí pé ìjì líle kan ń fẹ́.+ 19 Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti tukọ̀ tó nǹkan bíi máìlì mẹ́ta sí mẹ́rin,* wọ́n rí Jésù tó ń rìn lórí òkun, tó sì ń sún mọ́ ọkọ̀ ojú omi náà, ẹ̀rù sì bà wọ́n. 20 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù!”+ 21 Ìgbà yẹn ni wọ́n wá fẹ́ kó wọnú ọkọ̀ ojú omi náà, ọkọ̀ ojú omi náà sì dé ilẹ̀ tí wọ́n forí lé+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

22 Lọ́jọ́ kejì, àwọn èrò tó wà ní òdìkejì òkun rí i pé kò sí ọkọ̀ ojú omi níbẹ̀. Ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ Jésù ò bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ náà, torí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ló lọ. 23 Àmọ́, àwọn ọkọ̀ ojú omi láti Tìbéríà dé sí tòsí ibi tí wọ́n ti jẹ búrẹ́dì lẹ́yìn tí Olúwa dúpẹ́. 24 Torí náà, nígbà tí àwọn èrò náà rí i pé Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò sí níbẹ̀, wọ́n wọ àwọn ọkọ̀ ojú omi wọn wá sí Kápánáúmù láti wá Jésù.

25 Nígbà tí wọ́n rí i ní òdìkejì òkun, wọ́n bi í pé: “Rábì,+ ìgbà wo lo débí?” 26 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, kì í ṣe torí àwọn àmì tí ẹ rí lẹ ṣe ń wá mi, àmọ́ torí pé ẹ jẹ nínú àwọn búrẹ́dì náà, ẹ sì yó.+ 27 Ẹ má ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó ń ṣègbé, àmọ́ ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó wà fún ìyè àìnípẹ̀kun,+ èyí tí Ọmọ èèyàn máa fún yín; torí pé Baba, ìyẹn Ọlọ́run fúnra rẹ̀, ti gbé èdìdì ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ lé ẹni yìí.”+

28 Torí náà, wọ́n bi í pé: “Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti ṣe àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run?” 29 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Iṣẹ́ Ọlọ́run ni pé, kí ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tó rán.”+ 30 Torí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Iṣẹ́ àmì wo lo máa ṣe,+ ká lè rí i, ká sì gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ wo lo máa ṣe? 31 Àwọn baba ńlá wa jẹ mánà ní aginjù,+ bí a ṣe kọ ọ́ pé: ‘Ó fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run kí wọ́n lè jẹ.’”+ 32 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, Mósè ò fún yín ní oúnjẹ láti ọ̀run, àmọ́ Baba mi fún yín ní oúnjẹ tòótọ́ láti ọ̀run. 33 Torí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni ẹni tó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, tó sì fún ayé ní ìyè.” 34 Wọ́n wá sọ fún un pé: “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí.”

35 Jésù sọ fún wọn pé: “Èmi ni oúnjẹ ìyè. Ẹnikẹ́ni tó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi ò ní pa á rárá, ẹnikẹ́ni tó bá sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi, òùngbẹ ò ní gbẹ ẹ́ láé.+ 36 Àmọ́ bí mo ṣe sọ fún yín, àní ẹ ti rí mi, síbẹ̀ ẹ ò gbà gbọ́.+ 37 Gbogbo àwọn tí Baba fún mi máa wá sọ́dọ̀ mi, mi ò sì ní lé ẹni tó bá wá sọ́dọ̀ mi kúrò láé;+ 38 torí mi ò sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run+ kí n lè ṣe ìfẹ́ ara mi, ṣùgbọ́n láti ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi.+ 39 Ìfẹ́ ẹni tó rán mi ni pé kí n má pàdánù ìkankan nínú gbogbo àwọn tó fún mi, àmọ́ kí n jí wọn dìde + ní ọjọ́ ìkẹyìn. 40 Torí ìfẹ́ Baba mi ni pé kí gbogbo ẹni tó mọ Ọmọ, tó sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ màá sì jí i dìde+ ní ọjọ́ ìkẹyìn.”

41 Àwọn Júù wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí i torí ó sọ pé: “Èmi ni oúnjẹ tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run.”+ 42 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ṣebí Jésù ọmọ Jósẹ́fù nìyí, tí a mọ bàbá àti ìyá rẹ̀?+ Kí ló dé tó wá sọ pé, ‘Mo sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run’?” 43 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ má kùn láàárín ara yín mọ́. 44 Kò sí èèyàn tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba tó rán mi fà á,+ màá sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.+ 45 A kọ ọ́ sínú àwọn Wòlíì pé: ‘Jèhófà* máa kọ́ gbogbo wọn.’+ Gbogbo ẹni tó bá ti gbọ́ ti Baba, tó sì ti kẹ́kọ̀ọ́ ń wá sọ́dọ̀ mi. 46 Kì í ṣe pé èèyàn kankan ti rí Baba,+ àfi ẹni tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run; ẹni yìí ti rí Baba.+ 47 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gbà gbọ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun.+

48 “Èmi ni oúnjẹ ìyè.+ 49 Àwọn baba ńlá yín jẹ mánà ní aginjù, síbẹ̀ wọ́n kú.+ 50 Oúnjẹ tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run nìyí, kí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ nínú rẹ̀ má bàa kú. 51 Èmi ni oúnjẹ ààyè tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run. Tí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, ó máa wà láàyè títí láé; àti pé ní tòótọ́, ẹran ara mi ni oúnjẹ tí màá fúnni nítorí ìyè ayé.”+

52 Torí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn pé: “Báwo ni ọkùnrin yìí ṣe máa fún wa ní ẹran ara rẹ̀ jẹ?” 53 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ èèyàn, tí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ ò ní ìyè kankan nínú ara yín.+ 54 Ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ ẹran ara mi, tó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi máa ní ìyè àìnípẹ̀kun, màá sì jí i dìde+ ní ọjọ́ ìkẹyìn; 55 torí pé oúnjẹ tòótọ́ ni ẹran ara mi, ohun mímu tòótọ́ sì ni ẹ̀jẹ̀ mi. 56 Ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ ẹran ara mi, tó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, èmi náà sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀.+ 57 Bí Baba tó wà láàyè ṣe rán mi, tí mo sì wà láàyè nítorí Baba, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tó bá ń fi mí ṣe oúnjẹ máa wà láàyè nítorí mi.+ 58 Oúnjẹ tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run nìyí. Kò dà bí ìgbà tí àwọn baba ńlá yín jẹun, síbẹ̀ tí wọ́n kú. Ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ oúnjẹ yìí máa wà láàyè títí láé.”+ 59 Ó sọ àwọn nǹkan yìí nígbà tó ń kọ́ni nínú sínágọ́gù kan* ní Kápánáúmù.

60 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń dẹ́rù bani; kò ṣeé gbọ́ sétí!” 61 Àmọ́ Jésù mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ń kùn nípa èyí, ó wá sọ fún wọn pé: “Ṣé ó mú yín kọsẹ̀ ni? 62 Tí ẹ bá wá rí Ọmọ èèyàn tó ń gòkè lọ sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀ ńkọ́?+ 63 Ẹ̀mí ló ń fúnni ní ìyè;+ ẹran ara ò wúlò rárá. Ẹ̀mí àti ìyè ni àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín.+ 64 Àmọ́ àwọn kan wà nínú yín tí kò gbà gbọ́.” Torí pé láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Jésù ti mọ àwọn tí kò gbà gbọ́ àti ẹni tó máa dà á.+ 65 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún yín pé, kò sí ẹni tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba yọ̀ǹda fún un.”+

66 Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pa dà sídìí àwọn nǹkan tí wọ́n ti fi sílẹ̀,+ wọn ò sì bá a rìn mọ́. 67 Jésù wá sọ fún àwọn Méjìlá náà pé: “Ẹ̀yin ò fẹ́ lọ ní tiyín, àbí ẹ fẹ́ lọ?” 68 Símónì Pétérù dá a lóhùn pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta la máa lọ?+ Ìwọ lo ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.+ 69 A ti gbà gbọ́, a sì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”+ 70 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin méjìlá (12) yìí ni mo yàn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+ Síbẹ̀, abanijẹ́* ni ọ̀kan nínú yín.”+ 71 Ní tòótọ́, ọ̀rọ̀ Júdásì ọmọ Símónì Ìsìkáríọ́tù ló ń sọ, torí pé ẹni yìí máa dà á, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wà lára àwọn Méjìlá náà.+

7 Lẹ́yìn náà, Jésù ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ káàkiri* Gálílì, kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ní Jùdíà, torí àwọn Júù ń wá bí wọ́n á ṣe pa á.+ 2 Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn*+ tí àwọn Júù máa ń ṣe ti sún mọ́lé. 3 Torí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀+ sọ fún un pé: “Kúrò níbí, kí o sì lọ sí Jùdíà, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ náà lè rí àwọn iṣẹ́ tí ò ń ṣe. 4 Torí kò sí ẹni tí á máa ṣe ohunkóhun ní ìkọ̀kọ̀ tó bá fẹ́ kí wọ́n mọ òun ní gbangba. Tí o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, fi ara rẹ han ayé.” 5 Ní tòótọ́, àwọn arákùnrin rẹ̀ ò gbà á gbọ́.+ 6 Torí náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Àkókò mi ò tíì tó,+ àmọ́ gbogbo ìgbà ni àkókò wọ̀ fún yín. 7 Ayé ò ní ìdí kankan láti kórìíra yín, àmọ́ ó kórìíra mi, torí mò ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú.+ 8 Ẹ̀yin ẹ máa lọ síbi àjọyọ̀ náà; kò tíì yá fún mi láti lọ síbi àjọyọ̀ yìí, torí àkókò mi ò tíì tó ní kíkún.”+ 9 Torí náà, lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí fún wọn, ó dúró sí Gálílì.

10 Àmọ́ nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ ti lọ síbi àjọyọ̀ náà, òun náà wá lọ, àmọ́ kò lọ ní gbangba, ṣe ló yọ́ lọ. 11 Àwọn Júù wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá a níbi àjọyọ̀ náà, wọ́n ń sọ pé: “Ọkùnrin yẹn dà?” 12 Ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nípa rẹ̀ láàárín èrò. Àwọn kan á sọ pé: “Èèyàn dáadáa ni.” Àwọn míì á sọ pé: “Irọ́ ni. Ṣe ló ń tan àwọn èèyàn jẹ.”+ 13 Àmọ́ kò sí ẹni tó lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba torí wọ́n ń bẹ̀rù àwọn Júù.+

14 Nígbà tí wọ́n bá àjọyọ̀ náà dé ìdajì, Jésù gòkè lọ sínú tẹ́ńpìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni. 15 Ẹnu ya àwọn Júù, wọ́n sọ pé: “Báwo ni ọkùnrin yìí ṣe mọ Ìwé Mímọ́*+ tó báyìí láìjẹ́ pé ó lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́?”*+ 16 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, àmọ́ ó jẹ́ ti ẹni tó rán mi.+ 17 Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, ó máa mọ̀ bóyá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ náà ti wá+ àbí èrò ara mi ni mò ń sọ. 18 Ẹnikẹ́ni tó bá ń sọ èrò ara rẹ̀, ògo ara rẹ̀ ló ń wá; àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń wá ògo ẹni tó rán an,+ olóòótọ́ ni ẹni yìí, kò sì sí àìṣòdodo kankan nínú rẹ̀. 19 Mósè fún yín ní Òfin,+ àbí kò fún yín? Àmọ́ kò sí ìkankan nínú yín tó ń ṣègbọràn sí Òfin náà. Kí ló dé tí ẹ̀ ń wá bí ẹ ṣe máa pa mí?”+ 20 Àwọn èèyàn dáhùn pé: “Ẹlẹ́mìí èṣù ni ọ́. Ta ló fẹ́ pa ọ́?” 21 Jésù sọ fún wọn pé: “Iṣẹ́ kan ni mo ṣe tó ń ya gbogbo yín lẹ́nu. 22 Ìdí nìyí tí Mósè fi sọ pé kí ẹ máa dádọ̀dọ́*+—kì í ṣe pé ó wá látọ̀dọ̀ Mósè, àmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá ló ti wá+—ẹ sì ń dádọ̀dọ́ ọkùnrin ní sábáàtì. 23 Tí ọkùnrin kan bá dádọ̀dọ́ ní sábáàtì torí kó má bàa rú Òfin Mósè, ṣé ẹ wá ń bínú gidigidi sí mi ni, torí pé mo wo ọkùnrin kan sàn pátápátá ní sábáàtì?+ 24 Ẹ yéé fi ìrísí òde ṣe ìdájọ́, àmọ́ ẹ máa dá ẹjọ́ òdodo.”+

25 Àwọn kan lára àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ọkùnrin tí wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe fẹ́ pa nìyí, àbí òun kọ́?+ 26 Ẹ wò ó! òun ló ń sọ̀rọ̀ ní gbangba yìí, wọn ò sì sọ nǹkan kan sí i. Ṣé ó ti dá àwọn alákòóso lójú pé Kristi nìyí ni? 27 Ní tiwa, a mọ ibi tí ọkùnrin yìí ti wá;+ àmọ́ tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tó máa mọ ibi tó ti wá.” 28 Bí Jésù ṣe ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì, ó gbóhùn sókè, ó ní: “Ẹ mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá. Èmi kọ́ ni mo rán ara mi,+ Ẹni kan wà tí ó rán mi, ẹ ò sì mọ̀ ọ́n.+ 29 Èmi mọ̀ ọ́n,+ torí pé aṣojú látọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mí, Ẹni yẹn ló sì rán mi jáde.” 30 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa mú un,+ àmọ́ ẹnì kankan ò fọwọ́ kàn án, torí pé wákàtí rẹ̀ ò tíì tó.+ 31 Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn náà gbà á gbọ́,+ wọ́n sì ń sọ pé: “Tí Kristi bá dé, ṣé ó máa ṣe iṣẹ́ àmì tó ju èyí tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ ni?”

32 Àwọn Farisí gbọ́ tí àwọn èrò ń sọ àwọn nǹkan yìí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí sì rán àwọn òṣìṣẹ́ pé kí wọ́n lọ mú un.* 33 Jésù wá sọ pé: “Màá ṣì wà pẹ̀lú yín fúngbà díẹ̀ sí i, kí n tó lọ sọ́dọ̀ Ẹni tó rán mi.+ 34 Ẹ máa wá mi, àmọ́ ẹ ò ní rí mi, ẹ ò sì ní lè wá sí ibi tí mo wà.”+ 35 Torí náà, àwọn Júù sọ láàárín ara wọn pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí fẹ́ lọ, tí a ò fi ní rí i? Kì í ṣe ọ̀dọ̀ àwọn Júù tó fọ́n ká sáàárín àwọn Gíríìkì ló fẹ́ lọ, kó sì máa kọ́ àwọn Gíríìkì, àbí ohun tó fẹ́ ṣe nìyẹn ni? 36 Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé, ‘Ẹ máa wá mi, àmọ́ ẹ ò ní rí mi, ẹ ò sì ní lè wá sí ibi tí mo wà’?”

37 Ní ọjọ́ tó kẹ́yìn, ọjọ́ ńlá àjọyọ̀ náà,+ Jésù dìde, ó sì gbóhùn sókè, ó ní: “Tí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kó wá sọ́dọ̀ mi, kó sì mu.+ 38 Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ìwé mímọ́ ṣe sọ pé: ‘Láti inú rẹ̀ lọ́hùn-ún, omi ìyè máa ṣàn jáde.’”+ 39 Àmọ́ ó sọ èyí nípa ẹ̀mí tí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ máa tó gbà, torí kò tíì sí ẹ̀mí nígbà yẹn,+ torí pé a ò tíì ṣe Jésù lógo.+ 40 Àwọn kan láàárín èrò tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Wòlíì náà nìyí lóòótọ́.”+ 41 Àwọn míì ń sọ pé: “Kristi náà nìyí.”+ Àmọ́ àwọn kan ń sọ pé: “Gálílì kọ́ ni Kristi ti máa jáde wá, àbí ibẹ̀ ni?+ 42 Ṣebí ìwé mímọ́ sọ pé látinú ọmọ Dáfídì ni Kristi ti máa wá,+ ó sì máa wá láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ abúlé tí Dáfídì wà tẹ́lẹ̀?”+ 43 Àwọn èrò náà wá pínyà síra wọn nítorí rẹ̀. 44 Àwọn kan nínú wọn tiẹ̀ fẹ́ mú un,* àmọ́ ẹnì kankan ò fọwọ́ kàn án.

45 Àwọn òṣìṣẹ́ náà wá pa dà lọ bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí, wọ́n sì bi àwọn òṣìṣẹ́ náà pé: “Kí ló dé tí ẹ ò mú un wá?” 46 Àwọn òṣìṣẹ́ náà fèsì pé: “Èèyàn kankan ò sọ̀rọ̀ báyìí rí.”+ 47 Àwọn Farisí náà wá sọ pé: “Àbí wọ́n ti tan ẹ̀yin náà jẹ ni? 48 Kò sí ìkankan nínú àwọn alákòóso tàbí àwọn Farisí tó gbà á gbọ́, àbí ó wà?+ 49 Àmọ́ ẹni ègún ni àwọn èèyàn yìí tí wọn ò mọ Òfin.” 50 Nikodémù, ẹni tó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, tó sì wà lára wọn, sọ fún wọn pé: 51 “Òfin wa kì í ṣèdájọ́ èèyàn láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ gbọ́ tẹnu rẹ̀, kó sì mọ ohun tó ń ṣe, àbí ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?”+ 52 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Kì í ṣe Gálílì ni ìwọ náà ti wá, àbí ibẹ̀ ni? Wádìí, kí o sì rí i pé a ò ní mú wòlíì kankan wá láti Gálílì.”*

8 12 Jésù tún sọ fún wọn pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.+ Ó dájú pé ẹnikẹ́ni tó bá ń tẹ̀ lé mi kò ní rìn nínú òkùnkùn, àmọ́ ó máa ní ìmọ́lẹ̀+ ìyè.” 13 Torí náà, àwọn Farisí sọ fún un pé: “Ò ń jẹ́rìí nípa ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òótọ́.” 14 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Tí mo bá tiẹ̀ jẹ́rìí nípa ara mi, òótọ́ ni ẹ̀rí mi, torí mo mọ ibi tí mo ti wá àti ibi tí mò ń lọ.+ Àmọ́ ẹ̀yin ò mọ ibi tí mo ti wá àti ibi tí mò ń lọ. 15 Ẹ̀ ń dáni lẹ́jọ́ lọ́nà ti ẹran ara;*+ èmi kì í dá èèyàn kankan lẹ́jọ́. 16 Síbẹ̀, tí mo bá tiẹ̀ dáni lẹ́jọ́, òótọ́ ni ìdájọ́ mi, torí mi ò dá wà, àmọ́ Baba tó rán mi wà pẹ̀lú mi.+ 17 Bákan náà, a kọ ọ́ sínú Òfin yín pé: ‘Òótọ́ ni ẹ̀rí ẹni méjì.’+ 18 Mò ń jẹ́rìí nípa ara mi, Baba tó rán mi sì ń jẹ́rìí nípa mi.”+ 19 Wọ́n wá bi í pé: “Ibo ni Baba rẹ wà?” Jésù dáhùn pé: “Ẹ ò mọ̀ mí, ẹ ò sì mọ Baba mi.+ Ká ní ẹ mọ̀ mí ni, ẹ̀ bá mọ Baba mi náà.”+ 20 Ibi ìṣúra+ ló ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì. Àmọ́ kò sẹ́ni tó mú un, torí wákàtí rẹ̀ ò tíì tó.+

21 Ó tún sọ fún wọn pé: “Mò ń lọ, ẹ sì máa wá mi, síbẹ̀ inú ẹ̀ṣẹ̀ yín lẹ máa kú sí.+ Ẹ ò lè wá sí ibi tí mò ń lọ.”+ 22 Àwọn Júù wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Kò ní pa ara rẹ̀, àbí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀? Torí ó sọ pé, ‘Ẹ ò lè wá sí ibi tí mò ń lọ.’” 23 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ìsàlẹ̀ ni ẹ̀yin ti wá; èmi wá láti òkè.+ Inú ayé yìí lẹ ti wá; èmi ò wá látinú ayé yìí. 24 Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún yín pé: Inú ẹ̀ṣẹ̀ yín lẹ máa kú sí. Torí tí ẹ ò bá gbà gbọ́ pé èmi ni ẹni náà, inú ẹ̀ṣẹ̀ yín lẹ máa kú sí.” 25 Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé: “Ta ni ọ́?” Jésù dá wọn lóhùn pé: “Kí ni mo tiẹ̀ ń bá yín sọ̀rọ̀ fún? 26 Mo ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo fẹ́ sọ nípa yín, tí mo sì fẹ́ ṣèdájọ́ rẹ̀. Ní tòótọ́, olóòótọ́ ni Ẹni tó rán mi, àwọn ohun tí mo sì gbọ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mò ń sọ nínú ayé.”+ 27 Wọn ò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ nípa Baba ló ń sọ fún wọn. 28 Torí náà, Jésù sọ pé: “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti gbé Ọmọ èèyàn sókè,+ ìgbà yẹn lẹ máa wá mọ̀ pé èmi ni+ àti pé mi ò dá ṣe nǹkan kan lérò ara mi;+ àmọ́ bí Baba ṣe kọ́ mi gẹ́lẹ́ ni mò ń sọ àwọn nǹkan yìí. 29 Ẹni tó rán mi wà pẹ̀lú mi; kò pa mí tì lémi nìkan, torí gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣe ohun tó wù ú.”+ 30 Bó ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.

31 Jésù wá sọ fún àwọn Júù tó gbà á gbọ́ pé: “Tí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín lóòótọ́, 32 ẹ ó mọ òtítọ́,+ òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.”+ 33 Wọ́n sọ fún un pé: “Ọmọ Ábúráhámù ni wá, a ò sì ṣe ẹrú ẹnikẹ́ni rí. Kí ló dé tí o wá sọ pé, ‘Ẹ máa di òmìnira’?” 34 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀+ ni gbogbo ẹni tó bá ń dẹ́ṣẹ̀. 35 Bákan náà, ẹrú kì í wà nínú ilé títí láé, àmọ́ ọmọ máa ń wà níbẹ̀ títí láé. 36 Torí náà, tí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ máa di òmìnira lóòótọ́. 37 Mo mọ̀ pé ọmọ Ábúráhámù ni yín. Àmọ́ ẹ̀ ń wá bí ẹ ṣe máa pa mí, torí pé ọ̀rọ̀ mi ò ṣe yín láǹfààní kankan. 38 Mò ń sọ àwọn ohun tí mo ti rí nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ Baba mi,+ àmọ́ ohun tí ẹ̀yin gbọ́ látọ̀dọ̀ bàbá yín lẹ̀ ń ṣe.” 39 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Ábúráhámù ni bàbá wa.” Jésù sọ fún wọn pé: “Tó bá jẹ́ pé ọmọ Ábúráhámù ni yín,+ àwọn iṣẹ́ Ábúráhámù lẹ̀ bá máa ṣe. 40 Àmọ́ ní báyìí, ẹ̀ ń wá bí ẹ ṣe máa pa mí, èmi tí mo sọ òtítọ́ tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run+ fún yín. Ábúráhámù ò ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. 41 Àwọn iṣẹ́ bàbá yín lẹ̀ ń ṣe.” Wọ́n sọ fún un pé: “Ìṣekúṣe* kọ́ ni wọ́n fi bí wa; Baba kan la ní, Ọlọ́run ni.”

42 Jésù sọ fún wọn pé: “Tó bá jẹ́ Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ mi,+ torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mo ti wá, mo sì wà níbí. Èmi kọ́ ni mo rán ara mi wá, àmọ́ Ẹni yẹn ló rán mi.+ 43 Kí ló dé tí ohun tí mò ń sọ ò yé yín? Torí pé ẹ ò lè fetí sí ọ̀rọ̀ mi. 44 Ọ̀dọ̀ Èṣù bàbá yín lẹ ti wá, ẹ sì fẹ́ ṣe àwọn ìfẹ́ ọkàn bàbá yín.+ Apààyàn ni ẹni yẹn nígbà tó bẹ̀rẹ̀,*+ kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, torí pé òtítọ́ ò sí nínú rẹ̀. Tó bá ń pa irọ́, ṣe ló ń sọ irú ẹni tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́, torí pé òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́.+ 45 Àmọ́ torí pé èmi ń sọ òtítọ́, ẹ ò gbà mí gbọ́. 46 Èwo nínú yín ló dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Tó bá jẹ́ òtítọ́ ni mò ń sọ, kí ló dé tí ẹ ò gbà mí gbọ́? 47 Ẹni tó bá wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run máa ń fetí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.+ Ìdí nìyí tí ẹ ò fi fetí sílẹ̀, torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ lẹ ti wá.”+

48 Àwọn Júù dá a lóhùn pé: “Ṣebí a ti sọ pé, ‘Ará Samáríà ni ọ́,+ ẹlẹ́mìí èṣù sì ni ọ́’?”+ 49 Jésù fèsì pé: “Mi ò ní ẹ̀mí èṣù, àmọ́ mò ń bọlá fún Baba mi, ẹ̀yin sì ń kàn mí lábùkù. 50 Ṣùgbọ́n mi ò wá ògo fún ara mi;+ Ẹnì kan wà tó ń wá a, tó sì ń ṣèdájọ́. 51 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹnikẹ́ni bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ mi, kò ní rí ikú láé.”+ 52 Àwọn Júù sọ fún un pé: “A ti wá mọ̀ báyìí pé ẹlẹ́mìí èṣù ni ọ́. Ábúráhámù kú, àwọn wòlíì náà kú, àmọ́ ìwọ sọ pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ mi, kò ní tọ́ ikú wò láé.’ 53 O ò tóbi ju Ábúráhámù bàbá wa tó kú lọ, àbí o tóbi jù ú lọ? Àwọn wòlíì náà kú. Ta lò ń fi ara rẹ pè?” 54 Jésù dáhùn pé: “Tí mo bá ń ṣe ara mi lógo, ògo mi ò já mọ́ nǹkan kan. Baba mi ló ń ṣe mí lógo,+ ẹni tí ẹ sọ pé ó jẹ́ Ọlọ́run yín. 55 Síbẹ̀, ẹ ò tíì mọ̀ ọ́n,+ àmọ́ èmi mọ̀ ọ́n.+ Tí mo bá sì sọ pé mi ò mọ̀ ọ́n, ṣe ni màá dà bíi yín, ẹ̀yin òpùrọ́. Àmọ́ mo mọ̀ ọ́n, mo sì ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ̀. 56 Ábúráhámù bàbá yín yọ̀ gidigidi bó ṣe ń retí láti rí ọjọ́ mi, ó rí i, ó sì yọ̀.”+ 57 Àwọn Júù wá sọ fún un pé: “O ò tíì tó ẹni àádọ́ta (50) ọdún, síbẹ̀ o ti rí Ábúráhámù, àbí?” 58 Jésù sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, kí Ábúráhámù tó wà, èmi ti wà.”+ 59 Ni wọ́n bá ṣa òkúta kí wọ́n lè sọ ọ́ lù ú, àmọ́ Jésù fara pa mọ́, ó sì kúrò nínú tẹ́ńpìlì.

9 Bó ṣe ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní afọ́jú. 2 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá bi í pé: “Rábì,+ ta ló ṣẹ̀ tí wọ́n fi bí ọkùnrin yìí ní afọ́jú, ṣé òun ni àbí àwọn òbí rẹ̀?” 3 Jésù dáhùn pé: “Kì í ṣe ọkùnrin yìí ló ṣẹ̀, kì í sì í ṣe àwọn òbí rẹ̀, àmọ́ ó rí bẹ́ẹ̀ ká lè fi àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 4 A gbọ́dọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ Ẹni tó rán mi ní ojúmọmọ;+ òru ń bọ̀ nígbà tí èèyàn kankan ò ní lè ṣiṣẹ́. 5 Tí mo bá ṣì wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”+ 6 Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, ó tutọ́ sílẹ̀, ó pò ó mọ́ iyẹ̀pẹ̀, ó sì fi pa ojú ọkùnrin náà,+ 7 ó wá sọ fún un pé: “Lọ wẹ̀ nínú odò Sílóámù” (èyí tó túmọ̀ sí “Rán Jáde”). Torí náà, ó lọ wẹ̀, nígbà tó máa pa dà wá, ó ti ríran.+

8 Àwọn aládùúgbò àti àwọn tí wọ́n ti máa ń rí i tẹ́lẹ̀ pé alágbe ni wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ṣebí ọkùnrin tó máa ń jókòó ṣagbe nìyí, àbí òun kọ́?” 9 Àwọn kan ń sọ pé: “Òun ni.” Àwọn míì ń sọ pé: “Rárá o, àmọ́ ó jọ ọ́.” Ọkùnrin náà ń sọ ṣáá pé: “Èmi ni.” 10 Torí náà, wọ́n bi í pé: “Báwo wá ni ojú rẹ ṣe là?” 11 Ó dáhùn pé: “Ọkùnrin tí wọ́n ń pè ní Jésù ló po nǹkan kan, ó sì fi pa ojú mi, ó wá sọ fún mi pé, ‘Lọ wẹ̀ ní Sílóámù.’+ Mo wá lọ wẹ̀, mo sì ríran.” 12 Ni wọ́n bá sọ fún un pé: “Ibo ni ọkùnrin náà wà?” Ó sọ pé: “Mi ò mọ̀.”

13 Wọ́n mú ọkùnrin tó fìgbà kan jẹ́ afọ́jú náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisí. 14 Ó ṣẹlẹ̀ pé Sábáàtì+ ni ọjọ́ tí Jésù po itọ́ mọ́ iyẹ̀pẹ̀, tó sì la ojú rẹ̀.+ 15 Torí náà, lọ́tẹ̀ yìí, àwọn Farisí tún bẹ̀rẹ̀ sí í bi ọkùnrin náà nípa bó ṣe ríran. Ó sọ fún wọn pé: “Ó po nǹkan kan, ó sì fi sí ojú mi, mo wá lọ wẹ̀, mo sì ríran.” 16 Àwọn kan lára àwọn Farisí wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ ni ọkùnrin yìí ti wá, torí kì í pa Sábáàtì mọ́.”+ Àwọn míì sọ pé: “Báwo ni ọkùnrin tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ṣe irú àwọn iṣẹ́ àmì bẹ́ẹ̀?”+ Bí wọ́n ṣe pínyà síra wọn nìyẹn.+ 17 Wọ́n tún sọ fún ọkùnrin afọ́jú náà pé: “Nígbà tó jẹ́ pé ojú rẹ ni ọkùnrin náà là, kí lo máa sọ nípa rẹ̀?” Ọkùnrin náà sọ pé: “Wòlíì ni.”

18 Àmọ́ àwọn Júù ò gbà gbọ́ pé ó ti fọ́jú rí, pé ó sì ti pa dà ríran, àfìgbà tí wọ́n pe àwọn òbí ọkùnrin tó ti ń ríran náà. 19 Wọ́n bi wọ́n pé: “Ṣé ọmọ yín tí ẹ sọ pé ẹ bí ní afọ́jú nìyí? Báwo ló ṣe wá ń ríran?” 20 Àwọn òbí rẹ̀ dáhùn pé: “A mọ̀ pé ọmọ wa nìyí, afọ́jú la sì bí i. 21 Àmọ́ bó ṣe wá di pé ó ń ríran báyìí, àwa ò mọ̀; a ò sì mọ ẹni tó la ojú rẹ̀. Ẹ bi í. Kì í ṣe ọmọdé. Ẹ jẹ́ kó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.” 22 Ohun tó mú kí àwọn òbí rẹ̀ sọ àwọn nǹkan yìí ni pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn Júù,+ torí àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan tẹ́lẹ̀ pé, tí ẹnikẹ́ni bá gbà pé òun ni Kristi, wọ́n máa lé ẹni yẹn kúrò nínú sínágọ́gù.+ 23 Ìdí nìyí tí àwọn òbí rẹ̀ fi sọ pé: “Kì í ṣe ọmọdé. Ẹ bi í léèrè.”

24 Torí náà, wọ́n pe ọkùnrin tó fọ́jú tẹ́lẹ̀ náà lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì sọ fún un pé: “Fi ògo fún Ọlọ́run; a mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkùnrin yìí.” 25 Ó sọ pé: “Èmi ò mọ̀ bóyá ẹlẹ́ṣẹ̀ ni o. Ohun kan tí mo mọ̀ ni pé, afọ́jú ni mí tẹ́lẹ̀, àmọ́ mo ti ń ríran báyìí.” 26 Wọ́n wá bi í pé: “Kí ló ṣe fún ọ? Báwo ló ṣe la ojú rẹ?” 27 Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, àmọ́ ẹ ò fetí sílẹ̀. Kí lẹ tún fẹ́ gbọ́ ọ fún? Àbí ẹ̀yin náà fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni?” 28 Wọ́n wá sọ̀rọ̀ sí i tẹ̀gàntẹ̀gàn pé: “Ìwọ ni ọmọ ẹ̀yìn ọkùnrin yẹn, ọmọ ẹ̀yìn Mósè ni àwa. 29 A mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀, àmọ́ ní ti ọkùnrin yìí, a ò mọ ibi tó ti wá.” 30 Ọkùnrin náà sọ fún wọn pé: “Ọ̀rọ̀ yìí yà mí lẹ́nu o, pé ẹ ò mọ ibi tó ti wá, síbẹ̀ ó la ojú mi. 31 Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í tẹ́tí sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń bẹ̀rù Ọlọ́run, tó sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó máa ń tẹ́tí sí ẹni yìí.+ 32 Látìgbà láéláé, a ò gbọ́ ọ rí pé ẹnì kankan la ojú ẹni tí wọ́n bí ní afọ́jú. 33 Ká ní kì í ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí ti wá ni, kò ní lè ṣe nǹkan kan rárá.”+ 34 Wọ́n sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ tí wọ́n bí sínú ẹ̀ṣẹ̀ lódindi yìí lo tún fẹ́ máa kọ́ wa?” Ni wọ́n bá jù ú síta!+

35 Jésù gbọ́ pé wọ́n ti jù ú síta, nígbà tó sì rí i, ó sọ pé: “Ṣé o ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ èèyàn?” 36 Ọkùnrin náà dáhùn pé: “Ọ̀gá, ta ni onítọ̀hún, kí n lè ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?” 37 Jésù sọ fún un pé: “O ti rí i, kódà, òun ló ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.” 38 Ó sọ pé: “Mo ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, Olúwa.” Ó sì tẹrí ba* fún un. 39 Jésù wá sọ pé: “Torí ìdájọ́ yìí ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran,+ kí àwọn tó ríran sì lè di afọ́jú.”+ 40 Àwọn Farisí tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ àwọn nǹkan yìí, wọ́n sì sọ fún un pé: “Àwa náà ò fọ́jú, àbí a fọ́jú?” 41 Jésù sọ fún wọn pé: “Ká ní ẹ fọ́jú ni, ẹ ò ní dẹ́ṣẹ̀ kankan. Àmọ́ ní báyìí, ẹ sọ pé: ‘Àwa ríran.’ Ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣì ni yín.”+

10 “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹni tí kò bá gba ẹnu ọ̀nà wọ ọgbà àgùntàn, àmọ́ tó gba ibòmíì gòkè wọlé, olè àti akónilẹ́rù ni ẹni yẹn.+ 2 Àmọ́ ẹni tó bá gba ẹnu ọ̀nà wọlé ni olùṣọ́ àgùntàn.+ 3 Aṣọ́nà ṣílẹ̀kùn fún ẹni yìí,+ àwọn àgùntàn sì fetí sí ohùn rẹ̀.+ Ó ń fi orúkọ pe àwọn àgùntàn rẹ̀, ó sì ń kó wọn jáde. 4 Tó bá ti kó gbogbo àwọn tirẹ̀ jáde, ó máa ń lọ níwájú wọn, àwọn àgùntàn á sì tẹ̀ lé e, torí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. 5 Ó dájú pé wọn ò ní tẹ̀ lé àjèjì, ṣe ni wọ́n máa sá fún un, torí wọn ò mọ ohùn àwọn àjèjì.” 6 Jésù sọ àfiwé yìí fún wọn, àmọ́ ohun tó ń sọ fún wọn ò yé wọn.

7 Torí náà, Jésù tún sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, èmi ni ẹnu ọ̀nà fún àwọn àgùntàn.+ 8 Olè àti akónilẹ́rù ni gbogbo àwọn tó wá dípò mi; àmọ́ àwọn àgùntàn ò fetí sí wọn. 9 Èmi ni ẹnu ọ̀nà; ẹnikẹ́ni tó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé máa rí ìgbàlà, ẹni yẹn máa wọlé, ó máa jáde, ó sì máa rí ibi ìjẹko.+ 10 Olè kì í wá àfi tó bá fẹ́ jalè, kó pani, kó sì ba nǹkan jẹ́.+ Èmi wá, kí wọ́n lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní in lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ. 11 Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà;+ olùṣọ́ àgùntàn àtàtà máa ń fi ẹ̀mí* rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.+ 12 Nígbà tí alágbàṣe tí kì í ṣe olùṣọ́ àgùntàn, tí kì í sì í ṣe òun ló ni àwọn àgùntàn, rí ìkookò tó ń bọ̀, ó pa àwọn àgùntàn tì, ó sì sá lọ—ìkookò gbá wọn mú, ó sì tú wọn ká— 13 torí pé alágbàṣe ni, ọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn ò sì jẹ ẹ́ lógún. 14 Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà. Mo mọ àwọn àgùntàn mi, àwọn àgùntàn mi sì mọ̀ mí,+ 15 bí Baba ṣe mọ̀ mí, tí mo sì mọ Baba;+ mo fi ẹ̀mí* mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.+

16 “Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kò sí lára ọ̀wọ́ yìí;+ mo gbọ́dọ̀ mú àwọn yẹn náà wá, wọ́n á fetí sí ohùn mi, wọ́n á sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.+ 17 Ìdí nìyí tí Baba fi nífẹ̀ẹ́ mi,+ torí pé mo fi ẹ̀mí* mi lélẹ̀,+ kí n lè tún rí i gbà. 18 Kò sí èèyàn kankan tó gbà á lọ́wọ́ mi, èmi ni mo yọ̀ǹda láti fi lélẹ̀. Mo ní àṣẹ láti fi lélẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti tún un gbà.+ Ọwọ́ Baba mi ni mo ti gba àṣẹ yìí.”

19 Àwọn Júù tún pínyà síra wọn+ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ yìí. 20 Ọ̀pọ̀ nínú wọn ń sọ pé: “Ẹlẹ́mìí èṣù ni, orí rẹ̀ sì ti yí. Kí ló dé tí ẹ̀ ń fetí sí i?” 21 Àwọn míì sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ti ẹlẹ́mìí èṣù. Ẹ̀mí èṣù ò lè la ojú afọ́jú, àbí ó lè là á?”

22 Ní àkókò yẹn, Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́ wáyé ní Jerúsálẹ́mù. Ìgbà òtútù ni, 23 Jésù sì ń rìn nínú tẹ́ńpìlì ní ọ̀dẹ̀dẹ̀* Sólómọ́nì.+ 24 Ni àwọn Júù bá yí i ká, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé: “Títí dìgbà wo lo fẹ́ fi wá* sínú òkùnkùn? Tó bá jẹ́ ìwọ ni Kristi náà, sọ fún wa ní tààràtà.” 25 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Mo ti sọ fún yín, síbẹ̀ ẹ ò gbà gbọ́. Àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí nípa mi.+ 26 Àmọ́ ẹ ò gbà gbọ́, torí ẹ kì í ṣe àgùntàn mi.+ 27 Àwọn àgùntàn mi máa ń fetí sí ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi.+ 28 Mo fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ ó sì dájú pé wọn ò ní pa run láé, ẹnikẹ́ni ò sì ní já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi.+ 29 Ohun tí Baba mi ti fún mi tóbi ju gbogbo nǹkan míì lọ, kò sì sẹ́ni tó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba.+ 30 Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan.”*+

31 Ni àwọn Júù bá tún mú òkúta kí wọ́n lè sọ ọ́ lù ú. 32 Jésù sọ fún wọn pé: “Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fi hàn yín látọ̀dọ̀ Baba. Torí èwo nínú àwọn iṣẹ́ yìí lẹ ṣe fẹ́ sọ mí lókùúta?” 33 Àwọn Júù dá a lóhùn pé: “Kì í ṣe torí iṣẹ́ rere la ṣe fẹ́ sọ ọ́ lókùúta, torí ọ̀rọ̀ òdì ni;+ torí pé o ti sọ ara rẹ di ọlọ́run, ìwọ tó jẹ́ pé èèyàn ni ọ́.” 34 Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣebí a kọ ọ́ sínú Òfin yín pé, ‘Mo sọ pé: “ọlọ́run* ni yín”’?+ 35 Tó bá pe àwọn tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lòdì sí ní ‘ọlọ́run,’+ síbẹ̀ tí a kò lè wọ́gi lé ìwé mímọ́, 36 ṣé èmi tí Baba sọ di mímọ́, tó sì rán wá sí ayé lẹ wá ń sọ fún pé, ‘O sọ̀rọ̀ òdì,’ torí mo sọ pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni mí’?+ 37 Tí mi ò bá ṣe àwọn iṣẹ́ Baba mi, ẹ má gbà mí gbọ́. 38 Àmọ́ tí mo bá ń ṣe é, bí ẹ ò tiẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gba àwọn iṣẹ́ náà gbọ́,+ kí ẹ lè wá mọ̀, kí ẹ sì túbọ̀ máa mọ̀ pé Baba wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba.”+ 39 Ni wọ́n bá tún fẹ́ mú un, àmọ́ ó bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.

40 Ó tún lọ sí òdìkejì Jọ́dánì, síbi tí Jòhánù ti kọ́kọ́ ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn,+ ó sì dúró síbẹ̀. 41 Ọ̀pọ̀ èèyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Jòhánù ò ṣe iṣẹ́ àmì kankan, àmọ́ òótọ́ ni gbogbo ohun tí Jòhánù sọ nípa ọkùnrin yìí.”+ 42 Ọ̀pọ̀ èèyàn sì gbà á gbọ́ níbẹ̀.

11 Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Lásárù ń ṣàìsàn; Bẹ́tánì ló ti wá, ibẹ̀ ni abúlé Màríà àti Màtá+ arábìnrin rẹ̀. 2 Òun ni Màríà tó da òróró onílọ́fínńdà sí ara Olúwa, tó sì fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ;+ Lásárù arákùnrin rẹ̀ ló ń ṣàìsàn. 3 Torí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé: “Olúwa, wò ó! ẹni tí o nífẹ̀ẹ́ gan-an ń ṣàìsàn.” 4 Àmọ́ nígbà tí Jésù gbọ́, ó sọ pé: “Ikú kọ́ ló máa gbẹ̀yìn àìsàn yìí, àmọ́ ó jẹ́ fún ògo Ọlọ́run,+ ká lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.”

5 Jésù fẹ́ràn Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù. 6 Àmọ́ nígbà tó gbọ́ pé Lásárù ń ṣàìsàn, ó lo ọjọ́ méjì sí i níbi tó wà. 7 Lẹ́yìn èyí, ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ẹ jẹ́ ká tún lọ sí Jùdíà.” 8 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún un pé: “Rábì,+ ẹnu àìpẹ́ yìí ni àwọn ará Jùdíà fẹ́ sọ ọ́ lókùúta,+ ṣé o tún fẹ́ lọ síbẹ̀ ni?” 9 Jésù dáhùn pé: “Wákàtí méjìlá (12) ló wà ní ojúmọmọ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? + Tí ẹnikẹ́ni bá ń rìn ní ojúmọmọ, kì í kọ lu ohunkóhun, torí ó ń rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí. 10 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá ń rìn ní òru, ó máa kọsẹ̀, torí ìmọ́lẹ̀ kò sí nínú rẹ̀.”

11 Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, ó fi kún un pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti sùn,+ àmọ́ mò ń rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ kí n lè jí i.” 12 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ fún un pé: “Olúwa, tó bá jẹ́ pé ó ń sùn ni, ara rẹ̀ máa yá.” 13 Àmọ́, ọ̀rọ̀ ikú rẹ̀ ni Jésù ń sọ. Wọ́n rò pé ó sọ pé ó ń sùn kó lè sinmi. 14 Jésù wá sọ fún wọn ní tààràtà pé: “Lásárù ti kú,+ 15 mo sì yọ̀ nítorí yín pé mi ò sí níbẹ̀, kí ẹ lè gbà gbọ́. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” 16 Torí náà, Tọ́másì, tí wọ́n ń pè ní Ìbejì, sọ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, ká lè bá a kú.”+

17 Nígbà tí Jésù dé, ó rí i pé Lásárù ti wà nínú ibojì* náà fún ọjọ́ mẹ́rin. 18 Bẹ́tánì ò jìnnà sí Jerúsálẹ́mù, kò ju nǹkan bíi máìlì méjì* lọ síbẹ̀. 19 Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ti wá sọ́dọ̀ Màtá àti Màríà kí wọ́n lè tù wọ́n nínú torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin wọn. 20 Nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀; àmọ́ Màríà+ ṣì jókòó sílé. 21 Màtá wá sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú. 22 Síbẹ̀, mo ṣì mọ̀ pé ohunkóhun tí o bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run máa fún ọ.” 23 Jésù sọ fún un pé: “Arákùnrin rẹ máa dìde.” 24 Màtá sọ fún un pé: “Mo mọ̀ pé ó máa dìde nígbà àjíǹde+ ní ọjọ́ ìkẹyìn.” 25 Jésù sọ fún un pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.+ Ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, tó bá tiẹ̀ kú, ó máa yè; 26 gbogbo ẹni tó bá wà láàyè, tó sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi kò ní kú láé.+ Ṣé o gba èyí gbọ́?” 27 Ó sọ fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, mo ti gbà gbọ́ pé ìwọ ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tó ń bọ̀ wá sí ayé.” 28 Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó lọ pe Màríà arábìnrin rẹ̀, ó sọ fún un ní bòókẹ́lẹ́ pé: “Olùkọ́+ ti dé, ó ń pè ọ́.” 29 Bó ṣe gbọ́ èyí, ó yára dìde, ó sì lọ bá a.

30 Jésù ò tíì wọnú abúlé náà, ó ṣì wà níbi tí Màtá ti pàdé rẹ̀. 31 Nígbà tí àwọn Júù tó wà lọ́dọ̀ Màríà nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí i pé ó yára dìde, tó sì jáde, wọ́n tẹ̀ lé e torí wọ́n rò pé ibi ibojì*+ náà ló ń lọ láti lọ sunkún níbẹ̀. 32 Nígbà tí Màríà dé ibi tí Jésù wà, tó sì tajú kán rí i, ó kúnlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.” 33 Nígbà tí Jésù rí i tí òun àti àwọn Júù tó tẹ̀ lé e wá ń sunkún, ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi,* ìdààmú sì bá a. 34 Ó sọ pé: “Ibo lẹ tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n sọ fún un pé: “Olúwa, wá wò ó.” 35 Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú.+ 36 Ni àwọn Júù bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ẹ wò ó, ó mà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an o!” 37 Àmọ́ àwọn kan lára wọn sọ pé: “Ṣé ọkùnrin yìí tó la ojú ọkùnrin afọ́jú+ kò lè ṣe é kí ẹni yìí má kú ni?”

38 Lẹ́yìn tí ẹ̀dùn ọkàn tún bá Jésù, ó wá síbi ibojì* náà. Inú ihò kan ni, wọ́n sì fi òkúta kan dí i. 39 Jésù sọ pé: “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Màtá, arábìnrin olóògbé náà, sọ fún un pé: “Olúwa, á ti máa rùn báyìí, torí ó ti pé ọjọ́ mẹ́rin.” 40 Jésù sọ fún un pé: “Ṣebí mo sọ fún ọ pé tí o bá gbà gbọ́, o máa rí ògo Ọlọ́run?”+ 41 Torí náà, wọ́n gbé òkúta náà kúrò. Jésù wá gbójú sókè wo ọ̀run,+ ó sì sọ pé: “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti gbọ́ tèmi. 42 Lóòótọ́, mo mọ̀ pé o máa ń gbọ́ tèmi; àmọ́ torí èrò tó dúró yí ká ni mo fi sọ̀rọ̀, kí wọ́n lè gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi.”+ 43 Nígbà tó sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbóhùn sókè, ó sọ pé: “Lásárù, jáde wá!”+ 44 Ọkùnrin tó ti kú náà jáde wá, tòun ti aṣọ tí wọ́n fi dì í tọwọ́tẹsẹ̀ àti aṣọ tí wọ́n fi di ojú rẹ̀. Jésù sì sọ fún wọn pé: “Ẹ tú u, kí ẹ jẹ́ kó máa lọ.”

45 Torí náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù tí wọ́n wá sọ́dọ̀ Màríà, tí wọ́n sì rí ohun tó ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀,+ 46 àmọ́ àwọn kan lára wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisí, wọ́n sì sọ àwọn ohun tí Jésù ṣe fún wọn. 47 Torí náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí kó Sàhẹ́ndìrìn jọ, wọ́n sì sọ pé: “Kí ni ká ṣe, torí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì?+ 48 Tí a bá jẹ́ kó máa bá a lọ báyìí, gbogbo wọn ló máa gbà á gbọ́, àwọn ará Róòmù á sì wá gba àyè* wa àti orílẹ̀-èdè wa.” 49 Àmọ́ ọ̀kan lára wọn, Káyáfà,+ tó jẹ́ àlùfáà àgbà lọ́dún yẹn sọ fún wọn pé: “Ẹ ò mọ nǹkan kan rárá, 50 ẹ ò sì rò ó pé ó máa ṣe yín láǹfààní pé kí ọkùnrin kan kú torí àwọn èèyàn dípò kí gbogbo orílẹ̀-èdè pa run.” 51 Àmọ́ èrò ara rẹ̀ kọ́ ni ohun tó sọ yìí, ṣùgbọ́n torí pé òun ni àlùfáà àgbà lọ́dún yẹn, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa kú fún orílẹ̀-èdè náà, 52 kì í sì í ṣe fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, àmọ́ kó tún lè kó àwọn ọmọ Ọlọ́run tó ti fọ́n káàkiri jọ, kí wọ́n sì di ọ̀kan. 53 Torí náà, láti ọjọ́ yẹn lọ, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.

54 Torí ìyẹn, Jésù ò rìn káàkiri ní gbangba mọ́ láàárín àwọn Júù, àmọ́ ó kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè tó wà nítòsí aginjù, sí ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Éfúrémù,+ ó sì dúró síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn. 55 Ìrékọjá+ àwọn Júù ti sún mọ́lé, ọ̀pọ̀ èèyàn láti ìgbèríko sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù kó tó dìgbà Ìrékọjá kí wọ́n lè wẹ ara wọn mọ́ bí Òfin ṣe sọ. 56 Wọ́n ń wá Jésù, bí wọ́n sì ṣe dúró káàkiri nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n ń sọ fún ara wọn pé: “Kí lèrò yín? Ṣé pé kò ní wá síbi àjọyọ̀ yìí rárá?” 57 Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí ti pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá mọ ibi tí Jésù wà, kó wá sọ, kí wọ́n lè mú un.*

12 Nígbà tí Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jésù dé sí Bẹ́tánì, níbi tí Lásárù+ wà, ẹni tí Jésù jí dìde. 2 Torí náà, wọ́n se àsè oúnjẹ alẹ́ fún un níbẹ̀, Màtá ń gbé oúnjẹ wá fún wọn,+ Lásárù sì wà lára àwọn tó ń bá a jẹun.* 3 Màríà wá mú ìwọ̀n pọ́n-ùn kan* òróró onílọ́fínńdà, ojúlówó náádì tó wọ́n gan-an, ó dà á sí ẹsẹ̀ Jésù, ó sì fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ. Òórùn òróró onílọ́fínńdà náà wá gba inú ilé náà kan.+ 4 Àmọ́ Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tó máa tó dà á, sọ pé: 5 “Kí ló dé tí a ò ta òróró onílọ́fínńdà yìí ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) owó dínárì,* ká sì fún àwọn aláìní?” 6 Kì í ṣe torí pé ọ̀rọ̀ àwọn aláìní jẹ ẹ́ lógún ló ṣe sọ ọ̀rọ̀ yìí o, àmọ́ torí pé olè ni, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àpótí owó wà, ó sì máa ń jí owó inú rẹ̀. 7 Torí náà, Jésù sọ pé: “Fi í sílẹ̀, kó lè ṣe èyí nítorí ọjọ́ ìsìnkú mi.+ 8 Torí ìgbà gbogbo ni àwọn aláìní wà láàárín yín,+ àmọ́ ìgbà gbogbo kọ́ ni màá wà láàárín yín.”+

9 Ní àkókò yẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù gbọ́ pé ó wà níbẹ̀, wọ́n sì wá, àmọ́ kì í ṣe torí Jésù nìkan, wọ́n tún fẹ́ rí Lásárù, ẹni tí Jésù jí dìde.+ 10 Àwọn olórí àlùfáà wá gbìmọ̀ láti pa Lásárù náà, 11 ìdí ni pé torí rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù ṣe ń lọ síbẹ̀, tí wọ́n sì ń ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù.+

12 Lọ́jọ́ kejì, èrò rẹpẹtẹ tó wá síbi àjọyọ̀ náà gbọ́ pé Jésù ń bọ̀ ní Jerúsálẹ́mù. 13 Wọ́n wá mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “A bẹ̀ ọ́, gbà là! Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà,*+ Ọba Ísírẹ́lì!”+ 14 Nígbà tí Jésù rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó jókòó sórí rẹ̀,+ bí a ṣe kọ ọ́ pé: 15 “Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Síónì. Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀, ó jókòó sórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”*+ 16 Àwọn nǹkan yìí ò kọ́kọ́ yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àmọ́ nígbà tí a ṣe Jésù lógo,+ wọ́n rántí pé a ti kọ àwọn nǹkan yìí nípa rẹ̀ àti pé wọ́n ṣe àwọn nǹkan yìí sí i.+

17 Àwọn èrò tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tó pe Lásárù jáde látinú ibojì,*+ tó sì jí i dìde ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ ṣáá.+ 18 Ìdí nìyí tí àwọn èrò náà tún fi lọ bá a, torí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí. 19 Torí náà, àwọn Farisí sọ láàárín ara wọn pé: “Ṣé ẹ rí i pé ẹ ò ṣe àṣeyọrí kankan. Ẹ wò ó! Gbogbo ayé ti gba tiẹ̀.”+

20 Àwọn Gíríìkì kan wà lára àwọn tó wá jọ́sìn níbi àjọyọ̀ náà. 21 Torí náà, àwọn yìí wá bá Fílípì,+ ẹni tó wá láti Bẹtisáídà ti Gálílì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé: “Ọ̀gá, a fẹ́ rí Jésù.” 22 Fílípì wá, ó sì sọ fún Áńdérù. Áńdérù àti Fílípì wá sọ fún Jésù.

23 Àmọ́ Jésù dá wọn lóhùn pé: “Wákàtí náà ti dé tí a máa ṣe Ọmọ èèyàn lógo.+ 24 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, láìjẹ́ pé hóró àlìkámà* kan bọ́ sílẹ̀, kó sì kú, ó ṣì máa jẹ́ ẹyọ hóró kan ṣoṣo; àmọ́ tó bá kú,+ ìgbà yẹn ló máa so èso púpọ̀. 25 Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ràn ẹ̀mí* rẹ̀ ń pa á run, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá kórìíra ẹ̀mí* rẹ̀+ nínú ayé yìí máa pa á mọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.+ 26 Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìránṣẹ́ fún mi, kó máa tẹ̀ lé mi, ibi tí mo bá sì wà ni ìránṣẹ́ mi náà máa wà.+ Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìránṣẹ́ fún mi, Baba máa bọlá fún un. 27 Ní báyìí, ìdààmú bá mi,*+ kí sì ni kí n sọ? Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí.+ Síbẹ̀, torí èyí ni mo fi wá sí wákàtí yìí. 28 Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ni ohùn kan+ bá dún láti ọ̀run pé: “Mo ti ṣe é lógo, màá sì tún ṣe é lógo.”+

29 Àwọn èrò tó dúró síbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé ààrá ti sán. Àwọn míì sọ pé: “Áńgẹ́lì kan ti bá a sọ̀rọ̀.” 30 Jésù dáhùn pé: “Kì í ṣe torí tèmi ni ohùn yìí ṣe dún, torí tiyín ni. 31 Ní báyìí, à ń ṣèdájọ́ ayé yìí; ní báyìí, a máa lé alákòóso ayé yìí + jáde.+ 32 Síbẹ̀, tí a bá gbé mi sókè kúrò ní ayé,+ màá fa onírúurú èèyàn sọ́dọ̀ ara mi.” 33 Ní tòótọ́, ó ń sọ èyí láti jẹ́ kí wọ́n mọ irú ikú tó máa tó kú.+ 34 Àwọn èrò náà wá dá a lóhùn pé: “A gbọ́ látinú Òfin pé Kristi máa wà títí láé.+ Kí ló dé tí o wá sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ gbé Ọmọ èèyàn sókè?+ Ta ni Ọmọ èèyàn yìí?” 35 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ìmọ́lẹ̀ máa wà láàárín yín fúngbà díẹ̀ sí i. Ẹ rìn nígbà tí ẹ ṣì ní ìmọ́lẹ̀ náà, kí òkùnkùn má bàa borí yín; ẹnikẹ́ni tó bá ń rìn nínú òkùnkùn kò mọ ibi tí òun ń lọ.+ 36 Nígbà tí ẹ ṣì ní ìmọ́lẹ̀, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú ìmọ́lẹ̀ náà, kí ẹ lè di ọmọ ìmọ́lẹ̀.”+

Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ fara pa mọ́ fún wọn. 37 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì níwájú wọn, wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, 38 kí ọ̀rọ̀ wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé: “Jèhófà,* ta ló ti nígbàgbọ́ nínú ohun tó gbọ́ lọ́dọ̀ wa?*+ Ní ti apá Jèhófà,* ta la ti ṣí i payá fún?”+ 39 Ìdí tí wọn ò fi gbà gbọ́ ni pé Àìsáyà tún sọ pé: 40 “Ó ti fọ́ ojú wọn, ó sì ti mú kí ọkàn wọn le, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn ríran, kí ọkàn wọn má sì lóye, kí wọ́n lè yí pa dà, kí n sì mú wọn lára dá.”+ 41 Àìsáyà sọ àwọn nǹkan yìí torí pé ó rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.+ 42 Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú àwọn alákòóso pàápàá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lóòótọ́,+ àmọ́ wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí àwọn Farisí, kí wọ́n má bàa lé wọn kúrò nínú sínágọ́gù;+ 43 torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ògo èèyàn pàápàá ju ògo Ọlọ́run lọ.+

44 Àmọ́ Jésù gbóhùn sókè, ó sì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, kò ní ìgbàgbọ́ nínú èmi nìkan, àmọ́ ó tún ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tó rán mi;+ 45 ẹnikẹ́ni tó bá sì rí mi, ó rí Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.+ 46 Mo wá sínú ayé bí ìmọ́lẹ̀,+ kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú mi má bàa wà nínú òkùnkùn.+ 47 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa á mọ́, mi ò ní dá a lẹ́jọ́; torí pé mi ò wá láti dá ayé lẹ́jọ́, àmọ́ láti gba ayé là.+ 48 Ẹnikẹ́ni tí kò bá kà mí sí, tí kò sì gba àwọn ọ̀rọ̀ mi ní ẹni tó máa dá a lẹ́jọ́. Ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ ló máa dá a lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn. 49 Torí èrò ara mi kọ́ ni mò ń sọ, àmọ́ Baba tó rán mi fúnra rẹ̀ ti fún mi ní àṣẹ kan nípa ohun tí màá wí àti ohun tí màá sọ.+ 50 Mo sì mọ̀ pé àṣẹ rẹ̀ túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.+ Torí náà, ohunkóhun tí mo bá sọ, bí Baba ṣe sọ fún mi gẹ́lẹ́ ni mo sọ ọ́.”+

13 Torí pé Jésù ti mọ̀ ṣáájú àjọyọ̀ Ìrékọjá pé wákàtí òun ti tó+ láti kúrò ní ayé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba,+ ó nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tó wà ní ayé, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.+ 2 Wọ́n ń jẹ oúnjẹ alẹ́ lọ́wọ́, Èṣù sì ti fi sínú ọkàn Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ ọmọ Símónì, pé kó dà á.+ 3 Jésù mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́ àti pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun sì ń lọ,+ 4 torí náà, ó dìde nídìí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Ó wá mú aṣọ ìnura, ó sì so ó mọ́ ìbàdí.*+ 5 Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú bàsíà kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì ń fi aṣọ ìnura tó so mọ́ ìbàdí* nù ún gbẹ. 6 Ó wá dé ọ̀dọ̀ Símónì Pétérù. Ó bi í pé: “Olúwa, ṣé o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi ni?” 7 Jésù dá a lóhùn pé: “Ohun tí mò ń ṣe ò tíì yé ọ báyìí, àmọ́ lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, ó máa yé ọ.” 8 Pétérù sọ fún un pé: “O ò ní fọ ẹsẹ̀ mi láéláé.” Jésù dá a lóhùn pé: “Láìjẹ́ pé mo fọ ẹsẹ̀ rẹ,+ o ò ní ìpín kankan lọ́dọ̀ mi.” 9 Símónì Pétérù bá sọ fún un pé: “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan lo máa fọ̀, tún fọ ọwọ́ mi àti orí mi.” 10 Jésù sọ fún un pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti wẹ̀, kò nílò ju ká fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, torí ó mọ́ látòkè délẹ̀. Ẹ̀yin mọ́, àmọ́ kì í ṣe gbogbo yín.” 11 Torí ó mọ ẹni tó máa da òun.+ Ìdí nìyí tó fi sọ pé: “Kì í ṣe gbogbo yín lẹ mọ́.”

12 Lẹ́yìn tó fọ ẹsẹ̀ wọn tán, tó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ó pa dà jókòó* sídìí tábìlì, ó sì sọ fún wọn pé: “Ṣé ohun tí mo ṣe fún yín yé yín? 13 Ẹ̀ ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ òótọ́ lẹ sì sọ, torí ohun tí mo jẹ́ nìyẹn.+ 14 Torí náà, tí èmi, tí mo jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá fọ ẹsẹ̀ yín,+ ó yẹ* kí ẹ̀yin náà máa fọ ẹsẹ̀ ara yín.+ 15 Torí mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.+ 16 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹrú ò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, ẹni tí a rán jáde kò sì tóbi ju ẹni tó rán an. 17 Tí ẹ bá mọ àwọn nǹkan yìí, aláyọ̀ ni yín tí ẹ bá ń ṣe wọ́n.+ 18 Gbogbo yín kọ́ ni mò ń bá wí; mo mọ àwọn tí mo ti yàn. Àmọ́ èyí jẹ́ torí kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ+ pé: ‘Ẹni tí a jọ ń jẹun ti jìn mí lẹ́sẹ̀.’*+ 19 Láti ìsinsìnyí lọ, mò ń sọ fún yín kó tó ṣẹlẹ̀, kó lè jẹ́ pé tó bá ṣẹlẹ̀, ẹ máa lè gbà gbọ́ pé èmi ni ẹni náà.+ 20 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gba ẹni yòówù tí mo rán gba èmi náà,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí gba Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.”+

21 Lẹ́yìn tí Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ẹ̀dùn ọkàn bá a nínú ẹ̀mí, ó sì jẹ́rìí, ó sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ọ̀kan nínú yín máa dà mí.”+ 22 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bẹ̀rẹ̀ sí í wo ara wọn, torí ọ̀rọ̀ náà rú wọn lójú, wọn ò mọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.+ 23 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ẹni tí Jésù nífẹ̀ẹ́,+ jókòó* sí tòsí* Jésù. 24 Torí náà, Símónì Pétérù mi orí sí ẹni yìí, ó sì sọ fún un pé: “Sọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ fún wa.” 25 Ẹni yẹn wá fẹ̀yìn ti àyà Jésù, ó sì bi í pé: “Olúwa, ta ni?”+ 26 Jésù dáhùn pé: “Ẹni tí mo bá fún ní búrẹ́dì tí mo kì bọ inú abọ́ ni.”+ Torí náà, lẹ́yìn tó ki búrẹ́dì bọ inú abọ́, ó mú un fún Júdásì, ọmọ Símónì Ìsìkáríọ́tù. 27 Lẹ́yìn tí Júdásì gba búrẹ́dì náà, Sátánì wọ inú Júdásì.+ Torí náà, Jésù sọ fún un pé: “Tètè ṣe ohun tí ò ń ṣe kíákíá.” 28 Àmọ́ ìkankan nínú àwọn tó jókòó sídìí tábìlì ò mọ ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ fún un. 29 Àwọn kan tiẹ̀ ń rò pé torí pé ọwọ́ Júdásì ni àpótí owó wà,+ ṣe ni Jésù ń sọ fún un pé, “Ra àwọn nǹkan tí a máa fi ṣe àjọyọ̀ náà” tàbí pé kó fún àwọn aláìní ní nǹkan. 30 Torí náà, lẹ́yìn tó gba búrẹ́dì náà, ó jáde lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ilẹ̀ sì ti ṣú.+

31 Torí náà, lẹ́yìn tó jáde, Jésù sọ pé: “Ní báyìí, a ṣe Ọmọ èèyàn lógo,+ a sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe Ọlọ́run lógo. 32 Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa ṣe é lógo,+ ó sì máa ṣe é lógo lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 33 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ìgbà díẹ̀ sí i ni màá fi wà pẹ̀lú yín. Ẹ máa wá mi; bí mo sì ṣe sọ fún àwọn Júù pé, ‘Ẹ ò lè wá sí ibi tí mò ń lọ,’+ mò ń sọ fún ẹ̀yin náà báyìí. 34 Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín,+ kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín.+ 35 Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”+

36 Símónì Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, ibo lò ń lọ?” Jésù dáhùn pé: “O ò lè tẹ̀ lé mi lọ síbi tí mò ń lọ báyìí, àmọ́ o máa tẹ̀ lé mi tó bá yá.”+ 37 Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, kí ló dé tí mi ò lè tẹ̀ lé ọ báyìí? Màá fi ẹ̀mí* mi lélẹ̀ nítorí rẹ.”+ 38 Jésù dáhùn pé: “Ṣé o máa fi ẹ̀mí* rẹ lélẹ̀ nítorí mi? Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, ó dájú pé àkùkọ ò ní kọ tí wàá fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+

14 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín.+ Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run;+ ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú èmi náà. 2 Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùgbé* ló wà. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹ bá ti sọ fún yín, torí pé mò ń lọ kí n lè pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín.+ 3 Bákan náà, tí mo bá lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, màá tún pa dà wá, màá sì gbà yín sílé sọ́dọ̀ ara mi, kí ẹ̀yin náà lè wà ní ibi tí mo wà.+ 4 Ẹ mọ ọ̀nà ibi tí mò ń lọ.”

5 Tọ́másì+ sọ fún un pé: “Olúwa, a ò mọ ibi tó ò ń lọ. Báwo la ṣe fẹ́ mọ ọ̀nà ibẹ̀?”

6 Jésù sọ fún un pé: “Èmi ni ọ̀nà+ àti òtítọ́ + àti ìyè.+ Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.+ 7 Ká ní ẹ mọ̀ mí ni, ẹ̀ bá mọ Baba mi náà; láti ìsinsìnyí lọ, ẹ ti mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”+

8 Fílípì sọ fún un pé: “Olúwa, fi Baba hàn wá, ìyẹn sì máa tó wa.”

9 Jésù sọ fún un pé: “Fílípì, pẹ̀lú bó ṣe pẹ́ tó tí mo ti wà pẹ̀lú yín, ṣé o ò tíì mọ̀ mí ni? Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.+ Kí ló dé tí o wá sọ pé, ‘Fi Baba hàn wá’? 10 Ṣé o ò gbà pé mo wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba àti pé Baba wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ni?+ Kì í ṣe èrò ara mi+ ni àwọn nǹkan tí mò ń sọ fún yín, àmọ́ Baba tó ṣì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀. 11 Ẹ gbà mí gbọ́ pé mo wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba, Baba sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi; tàbí kẹ̀, kí ẹ gbà gbọ́ nítorí àwọn iṣẹ́ náà fúnra wọn.+ 12 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi náà máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; ó sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ,+ torí pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba.+ 13 Bákan náà, ohunkóhun tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, màá ṣe é, ká lè tipasẹ̀ Ọmọ+ yin Baba lógo. 14 Tí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, màá ṣe é.

15 “Tí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́.+ 16 Màá béèrè lọ́wọ́ Baba, ó sì máa fún yín ní olùrànlọ́wọ́* míì tó máa wà pẹ̀lú yín títí láé,+ 17 ẹ̀mí òtítọ́,+ tí ayé ò lè gbà, torí pé kò rí i, kò sì mọ̀ ọ́n.+ Ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, torí ó wà pẹ̀lú yín, ó sì wà nínú yín. 18 Mi ò ní fi yín sílẹ̀ ní ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀.* Mò ń bọ̀ lọ́dọ̀ yín.+ 19 Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ayé ò ní rí mi mọ́, àmọ́ ẹ máa rí mi,+ torí pé mo wà láàyè, ẹ sì máa wà láàyè. 20 Ọjọ́ yẹn lẹ máa mọ̀ pé mo wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba mi àti pé ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín.+ 21 Ẹnikẹ́ni tó bá ní àwọn àṣẹ mi, tó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ẹni tó nífẹ̀ẹ́ mi. Lọ́wọ́ kejì, ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ mi, Baba mi máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, èmi náà máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, màá sì fi ara mi hàn án kedere.”

22 Júdásì,+ tí kì í ṣe Ìsìkáríọ́tù, sọ fún un pé: “Olúwa, kí ló ṣẹlẹ̀ tó fi jẹ́ pé àwa lo fẹ́ fi ara rẹ hàn kedere sí, tí kì í ṣe ayé?”

23 Jésù dá a lóhùn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, ó máa pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,+ Baba mi sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a máa wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì máa fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé* wa.+ 24 Ẹnikẹ́ni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ mi kì í pa àwọn ọ̀rọ̀ mi mọ́. Ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń gbọ́ kì í ṣe tèmi, àmọ́ ó jẹ́ ti Baba tó rán mi.+

25 “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín nígbà tí mo ṣì wà pẹ̀lú yín. 26 Àmọ́ olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, tí Baba máa rán ní orúkọ mi, máa kọ́ yín ní gbogbo nǹkan, ó sì máa rán yín létí gbogbo ohun tí mo sọ fún yín.+ 27 Mo fi àlàáfíà sílẹ̀ fún yín; mo fún yín ní àlàáfíà mi.+ Mi ò fún yín lọ́nà tí ayé gbà ń fúnni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín, kí ìbẹ̀rù má sì mú kí ọkàn yín dà rú. 28 Ẹ gbọ́ tí mo sọ fún yín pé, ‘Mò ń lọ, mo sì ń pa dà bọ̀ sọ́dọ̀ yín.’ Tí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, inú yín máa dùn pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, torí pé Baba tóbi jù mí lọ.+ 29 Torí náà, mo ti sọ fún yín báyìí kó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè gbà gbọ́ tó bá ṣẹlẹ̀.+ 30 Mi ò ní bá yín sọ̀rọ̀ púpọ̀ mọ́, torí alákòóso ayé+ ń bọ̀, kò sì ní agbára kankan lórí mi.*+ 31 Àmọ́ torí kí ayé lè mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Baba, ohun tí Baba pa láṣẹ fún mi pé kí n ṣe gẹ́lẹ́ ni mò ń ṣe.+ Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká kúrò níbí.

15 “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni ẹni tó ń dáko. 2 Ó ń mú gbogbo ẹ̀ka tí kì í so èso nínú mi kúrò, ó sì ń wẹ gbogbo èyí tó ń so èso mọ́, kó lè so èso púpọ̀ sí i.+ 3 Ẹ ti mọ́ torí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín.+ 4 Ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, màá sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín. Bí ẹ̀ka ò ṣe lè dá so èso àfi tó bá dúró lára àjàrà, ẹ̀yin náà ò lè ṣe bẹ́ẹ̀, àfi tí ẹ bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi.+ 5 Èmi ni àjàrà náà; ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹnikẹ́ni tó bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, ẹni yìí ń so èso púpọ̀;+ torí láìsí èmi, ẹ ò lè ṣe ohunkóhun. 6 Tí ẹnikẹ́ni ò bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, a máa sọ ọ́ nù bí ẹ̀ka, á sì gbẹ. Àwọn èèyàn á kó àwọn ẹ̀ka yẹn jọ, wọ́n á sọ wọ́n sínú iná, wọ́n á sì jóná. 7 Tí ẹ bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí àwọn ọ̀rọ̀ mi sì wà nínú yín, ẹ béèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, ó sì máa rí bẹ́ẹ̀ fún yín.+ 8 Èyí ń fògo fún Baba mi, pé ẹ̀ ń so èso púpọ̀, ẹ sì fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín.+ 9 Bí Baba ṣe nífẹ̀ẹ́ mi,+ èmi náà nífẹ̀ẹ́ yín; ẹ dúró nínú ìfẹ́ mi. 10 Tí ẹ bá ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ máa dúró nínú ìfẹ́ mi, bí mo ṣe pa àwọn àṣẹ Baba mọ́ gẹ́lẹ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.

11 “Mo sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kí ayọ̀ mi lè wà nínú yín, kí ayọ̀ yín sì lè kún rẹ́rẹ́.+ 12 Àṣẹ mi nìyí, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.+ 13 Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ẹ̀mí* rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.+ 14 Ọ̀rẹ́ mi ni yín, tí ẹ bá ń ṣe ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín.+ 15 Mi ò pè yín ní ẹrú mọ́, torí pé ẹrú kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Àmọ́ mo pè yín ní ọ̀rẹ́, torí pé mo ti jẹ́ kí ẹ mọ gbogbo ohun tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba mi. 16 Ẹ̀yin kọ́ lẹ yàn mí, èmi ni mo yàn yín, mo sì yàn yín pé kí ẹ lọ, kí ẹ túbọ̀ máa so èso, kí èso yín ṣì máa wà, kó lè jẹ́ pé tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, ó máa fún yín.+

17 “Mò ń pa àwọn nǹkan yìí láṣẹ fún yín, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín.+ 18 Tí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kó tó kórìíra yín.+ 19 Tí ẹ bá jẹ́ apá kan ayé, ayé máa nífẹ̀ẹ́ ohun tó jẹ́ tirẹ̀. Torí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé,+ àmọ́ mo ti yàn yín látinú ayé, torí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín.+ 20 Ẹ fi ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín sọ́kàn pé: Ẹrú ò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Tí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n máa ṣe inúnibíni sí ẹ̀yin náà;+ tí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n máa pa ọ̀rọ̀ yín náà mọ́. 21 Àmọ́ wọ́n máa ṣe gbogbo nǹkan yìí sí yín nítorí orúkọ mi, torí pé wọn ò mọ Ẹni tó rán mi.+ 22 Ká ní mi ò wá bá wọn sọ̀rọ̀ ni, wọn ò ní ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan.+ Àmọ́ ní báyìí, wọn ò ní àwíjàre kankan fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+ 23 Ẹnikẹ́ni tó bá kórìíra mi kórìíra Baba mi náà.+ 24 Ká ní mi ò ṣe àwọn iṣẹ́ tí ẹnì kankan ò ṣe rí láàárín wọn ni, wọn ò ní ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan;+ àmọ́ ní báyìí wọ́n ti rí mi, wọ́n sì ti kórìíra èmi àti Baba mi. 25 Àmọ́ èyí ṣẹlẹ̀ torí kí ọ̀rọ̀ tí a kọ sínú Òfin wọn lè ṣẹ pé: ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’+ 26 Nígbà tí olùrànlọ́wọ́ tí màá rán sí yín látọ̀dọ̀ Baba bá dé, ẹ̀mí òtítọ́,+ tó wá látọ̀dọ̀ Baba, ó máa jẹ́rìí nípa mi;+ 27 kí ẹ̀yin náà sì jẹ́rìí,+ torí pé ẹ ti wà pẹ̀lú mi láti ìbẹ̀rẹ̀.

16 “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kí ẹ má bàa kọsẹ̀. 2 Àwọn èèyàn máa lé yín kúrò nínú sínágọ́gù.+ Kódà, wákàtí náà ń bọ̀, nígbà tí ẹnikẹ́ni tó bá pa yín+ máa rò pé ṣe lòun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run. 3 Àmọ́ wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan yìí torí pé wọn ò tíì wá mọ Baba, wọn ò sì tíì wá mọ̀ mí.+ 4 Síbẹ̀, mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kó lè jẹ́ pé tí wákàtí tí wọ́n máa ṣẹlẹ̀ bá dé, ẹ máa rántí pé mo sọ fún yín.+

“Mi ò kọ́kọ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, torí mo wà pẹ̀lú yín. 5 Àmọ́ ní báyìí, mò ń lọ sọ́dọ̀ Ẹni tó rán mi;+ síbẹ̀ ìkankan nínú yín ò bi mí pé, ‘Ibo lò ń lọ?’ 6 Àmọ́ torí pé mo sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, ẹ̀dùn ọkàn ti bá yín gidigidi.+ 7 Síbẹ̀, òótọ́ ni mò ń sọ fún yín, torí yín ni mo ṣe ń lọ. Ìdí ni pé tí mi ò bá lọ, olùrànlọ́wọ́ náà+ ò ní wá sọ́dọ̀ yín; àmọ́ tí mo bá lọ, màá rán an sí yín. 8 Tí ó bá sì dé, ó máa fún ayé ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀, nípa òdodo àti nípa ìdájọ́: 9 lákọ̀ọ́kọ́, nípa ẹ̀ṣẹ̀,+ torí pé wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú mi;+ 10 lẹ́yìn náà, nípa òdodo, torí pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ ò sì ní rí mi mọ́; 11 lẹ́yìn náà, nípa ìdájọ́, torí pé a ti dá alákòóso ayé yìí lẹ́jọ́.+

12 “Mo ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo fẹ́ sọ fún yín, àmọ́ ẹ ò ní lè gbà á báyìí. 13 Àmọ́ tí ìyẹn* bá dé, ẹ̀mí òtítọ́,+ ó máa darí yín sínú gbogbo òtítọ́, torí kì í ṣe èrò ara rẹ̀ ló máa sọ, àmọ́ ohun tó gbọ́ ló máa sọ, ó sì máa kéde àwọn nǹkan tó ń bọ̀ fún yín.+ 14 Ó máa yìn mí lógo,+ torí pé ó máa gbà lára ohun tó jẹ́ tèmi, ó sì máa kéde rẹ̀ fún yín.+ 15 Gbogbo ohun tí Baba ní jẹ́ tèmi.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ pé ó máa gbà lára ohun tó jẹ́ tèmi, ó sì máa kéde rẹ̀ fún yín. 16 Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi mọ́,+ bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi.”

17 Ni àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá sọ fún ara wọn pé: “Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún wa pé, ‘Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi, bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi’ àti pé, ‘torí pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba?” 18 Torí náà, wọ́n ń sọ pé: “Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé, ‘ní ìgbà díẹ̀ sí i’? A ò mọ ohun tó ń sọ.” 19 Jésù mọ̀ pé wọ́n fẹ́ bi òun ní ìbéèrè, torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ṣé torí mo sọ pé: ‘Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi, bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi,’ lẹ ṣe ń bi ara yín lọ́rọ̀ yìí? 20 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹ máa sunkún, ẹ sì máa pohùn réré ẹkún, àmọ́ ayé máa yọ̀; ẹ̀dùn ọkàn máa bá yín, àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn yín máa di ayọ̀.+ 21 Tí obìnrin kan bá fẹ́ bímọ, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá a torí pé wákàtí rẹ̀ ti tó, àmọ́ tó bá ti bí ọmọ náà, kò ní rántí ìpọ́njú náà mọ́ torí inú rẹ̀ máa dùn pé a ti bí ọmọ kan sí ayé. 22 Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, ẹ̀dùn ọkàn bá yín báyìí; àmọ́ màá tún rí yín, inú yín sì máa dùn,+ ẹnì kankan ò sì ní gba ayọ̀ yín mọ́ yín lọ́wọ́. 23 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ ò ní bi mí ní ìbéèrè kankan rárá. Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba,+ ó máa fún yín ní orúkọ mi.+ 24 Títí di báyìí, ẹ ò tíì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi. Ẹ béèrè, ẹ sì máa rí gbà, kí ayọ̀ yín lè kún rẹ́rẹ́.

25 “Àfiwé ni mo fi sọ àwọn nǹkan yìí fún yín. Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí mi ò ní lo àfiwé láti bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, àmọ́ màá sọ fún yín nípa Baba lọ́nà tó ṣe kedere. 26 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ máa béèrè nǹkan lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi; ohun tí mo sọ yìí ò túmọ̀ sí pé màá bá yín béèrè. 27 Torí Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín, torí pé ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi,+ ẹ sì ti gbà gbọ́ pé mo wá bí aṣojú Ọlọ́run.+ 28 Mo wá bí aṣojú Baba, mo sì ti wá sí ayé. Mo ti wá ń kúrò ní ayé báyìí, mo sì ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”+

29 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé: “Wò ó! Ọ̀rọ̀ rẹ ti ṣe kedere báyìí, o ò lo àfiwé. 30 A ti wá mọ̀ báyìí pé o mọ ohun gbogbo, o ò sì nílò kí ẹnikẹ́ni bi ọ́ ní ìbéèrè. Èyí mú ká gbà gbọ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lo ti wá.” 31 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ ti gbà gbọ́ báyìí? 32 Ẹ wò ó! Wákàtí náà ń bọ̀, ní tòótọ́, ó ti dé, nígbà tí wọ́n máa tú ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ká sí ilé rẹ̀, ẹ sì máa fi èmi nìkan sílẹ̀.+ Àmọ́ mi ò dá wà, torí pé Baba wà pẹ̀lú mi.+ 33 Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín kí ẹ lè ní àlàáfíà nípasẹ̀ mi.+ Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”+

17 Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbójú sókè wo ọ̀run, ó sọ pé: “Baba, wákàtí náà ti dé. Ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo,+ 2 bí o ṣe fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹran ara,*+ kó lè fún gbogbo àwọn tí o ti fún un+ ní ìyè àìnípẹ̀kun.+ 3 Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun,+ pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo*+ àti Jésù Kristi,+ ẹni tí o rán. 4 Mo ti yìn ọ́ lógo ní ayé,+ ní ti pé mo ti parí iṣẹ́ tí o ní kí n ṣe.+ 5 Torí náà, ní báyìí, Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.+

6 “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn èèyàn tí o fún mi látinú ayé.*+ Ìwọ lo ni wọ́n, o sì fi wọ́n fún mi, wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.* 7 Wọ́n ti wá mọ̀ báyìí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni gbogbo ohun tí o fún mi ti wá; 8 torí pé àwọn ọ̀rọ̀ tí o sọ fún mi ni mo ti sọ fún wọn,+ wọ́n sì ti gbà á, ó dájú pé wọ́n ti wá mọ̀ pé mo wá bí aṣojú rẹ,+ wọ́n sì ti gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi.+ 9 Mo gbàdúrà nípa wọn; kì í ṣe nípa ayé, àmọ́ nípa àwọn tí o fún mi, torí pé ìwọ lo ni wọ́n; 10 ìwọ lo ni gbogbo ohun tí mo ní, èmi ni mo sì ni tìrẹ,+ a sì ti ṣe mí lógo láàárín wọn.

11 “Mi ò sí ní ayé mọ́, àmọ́ àwọn wà ní ayé,+ mo sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn+ nítorí orúkọ rẹ, tí o ti fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan* bí àwa ṣe jẹ́ ọ̀kan.*+ 12 Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn, mo máa ń ṣọ́ wọn+ nítorí orúkọ rẹ, tí o ti fún mi; mo ti dáàbò bò wọ́n, ìkankan nínú wọn ò sì pa run+ àfi ọmọ ìparun,+ kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ.+ 13 Àmọ́ ní báyìí, mò ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ, mo sì ń sọ àwọn nǹkan yìí ní ayé, kí wọ́n lè ní ayọ̀ mi ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ nínú wọn.+ 14 Mo ti sọ ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn, àmọ́ ayé ti kórìíra wọn, torí wọn kì í ṣe apá kan ayé,+ bí èmi ò ṣe jẹ́ apá kan ayé.

15 “Mi ò ní kí o mú wọn kúrò ní ayé, àmọ́ kí o máa ṣọ́ wọn torí ẹni burúkú náà.+ 16 Wọn kì í ṣe apá kan ayé,+ bí èmi ò ṣe jẹ́ apá kan ayé.+ 17 Sọ wọ́n di mímọ́* nípasẹ̀ òtítọ́;+ òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.+ 18 Bí o ṣe rán mi wá sí ayé, èmi náà rán wọn lọ sínú ayé.+ 19 Mo sì ń sọ ara mi di mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn náà di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́.

20 “Kì í ṣe àwọn yìí nìkan ni mò ń gbàdúrà nípa wọn, mo tún ń gbàdúrà nípa àwọn tó máa ní ìgbàgbọ́ nínú mi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn, 21 kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan,+ bí ìwọ Baba ṣe wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ,+ kí àwọn náà lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa, kí ayé lè gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi. 22 Mo ti fún wọn ní ògo tí o fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan bí àwa ṣe jẹ́ ọ̀kan.+ 23 Èmi wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn, ìwọ sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, kí a lè mú kí wọ́n jẹ́ ọ̀kan délẹ̀délẹ̀,* kí ayé lè mọ̀ pé ìwọ lo rán mi àti pé o nífẹ̀ẹ́ wọn bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ mi. 24 Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fún mi wà pẹ̀lú mi níbi tí mo bá wà,+ kí wọ́n lè rí ògo mi tí o ti fún mi, torí pé o ti nífẹ̀ẹ́ mi ṣáájú kí o tó pilẹ̀ ayé.+ 25 Baba olódodo, ní tòótọ́, ayé ò tíì wá mọ̀ ọ́,+ àmọ́ èmi mọ̀ ọ́,+ àwọn yìí sì ti wá mọ̀ pé ìwọ lo rán mi. 26 Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n,+ kí ìfẹ́ tí o ní fún mi lè wà nínú wọn, kí n sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn.”+

18 Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí òdìkejì Àfonífojì Kídírónì,*+ níbi tí ọgbà kan wà, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wọnú ibẹ̀.+ 2 Júdásì, ẹni tó dà á náà mọ ibẹ̀, torí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sábà máa ń pàdé níbẹ̀. 3 Torí náà, Júdásì kó àwùjọ àwọn ọmọ ogun àti àwọn òṣìṣẹ́ ti àwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí, wọ́n sì wá síbẹ̀, tàwọn ti ògùṣọ̀, fìtílà àti ohun ìjà.+ 4 Jésù mọ gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun, torí náà, ó bọ́ síwájú, ó sì sọ fún wọn pé: “Ta lẹ̀ ń wá?” 5 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.”+ Ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni.” Júdásì, ẹni tó dà á náà wà ní ìdúró pẹ̀lú wọn.+

6 Àmọ́ nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé, “Èmi ni,” wọ́n sún mọ́ ẹ̀yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀.+ 7 Torí náà, ó tún bi wọ́n pé: “Ta lẹ̀ ń wá?” Wọ́n ní: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.” 8 Jésù dáhùn pé: “Mo ti sọ fún yín pé èmi ni. Torí náà, tó bá jẹ́ èmi lẹ̀ ń wá, ẹ fi àwọn yìí sílẹ̀.” 9 Èyí jẹ́ torí kí ohun tó sọ lè ṣẹ, pé: “Mi ò pàdánù ìkankan nínú àwọn tí o fún mi.”+

10 Ni Símónì Pétérù tó ní idà bá fà á yọ, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó gé etí rẹ̀ ọ̀tún dà nù.+ Málíkọ́sì ni orúkọ ẹrú náà. 11 Àmọ́ Jésù sọ fún Pétérù pé: “Fi idà náà sínú àkọ̀ rẹ̀.+ Ṣé kò yẹ kí n mu ife tí Baba fún mi ni?”+

12 Àwọn ọmọ ogun náà àti ọ̀gágun àti àwọn aláṣẹ àwọn Júù wá mú* Jésù, wọ́n sì dè é. 13 Wọ́n kọ́kọ́ mú un lọ sọ́dọ̀ Ánásì, torí òun ni bàbá ìyàwó Káyáfà,+ tó jẹ́ àlùfáà àgbà lọ́dún yẹn.+ 14 Ní tòótọ́, Káyáfà ló gba àwọn Júù nímọ̀ràn pé ó máa ṣe wọ́n láǹfààní kí ọkùnrin kan kú torí àwọn èèyàn.+

15 Símónì Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn míì ń tẹ̀ lé Jésù.+ Àlùfáà àgbà mọ ọmọ ẹ̀yìn yẹn, ó sì bá Jésù lọ sínú àgbàlá àlùfáà àgbà, 16 àmọ́ Pétérù dúró síta níbi ilẹ̀kùn.* Torí náà, ọmọ ẹ̀yìn kejì, tí àlùfáà àgbà mọ̀, jáde lọ bá aṣọ́nà sọ̀rọ̀, ó sì mú Pétérù wọlé. 17 Ìránṣẹ́bìnrin tó jẹ́ aṣọ́nà wá sọ fún Pétérù pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ọkùnrin yìí ni ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Ó sọ pé: “Rárá o.”+ 18 Àwọn ẹrú àti àwọn òṣìṣẹ́ dúró yí ká iná èédú tí wọ́n dá, torí pé òtútù mú, wọ́n sì ń yáná. Pétérù náà dúró síbẹ̀, ó sì ń yáná.

19 Torí náà, olórí àlùfáà bi Jésù léèrè nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. 20 Jésù dá a lóhùn pé: “Mo ti bá ayé sọ̀rọ̀ ní gbangba. Gbogbo ìgbà ni mò ń kọ́ni nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì,+ níbi tí gbogbo àwọn Júù ń kóra jọ sí; mi ò sì sọ ohunkóhun ní ìkọ̀kọ̀. 21 Kí ló dé tí ò ń bi mí? Bi àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí mo sọ fún wọn. Wò ó! Àwọn yìí mọ ohun tí mo sọ.” 22 Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ tó dúró nítòsí gbá Jésù létí,+ ó sì sọ pé: “Ṣé bí o ṣe máa dá olórí àlùfáà lóhùn nìyẹn?” 23 Jésù dá a lóhùn pé: “Tó bá jẹ́ ohun tí kò tọ́ ni mo sọ, jẹ́rìí nípa* ohun tí kò tọ́ náà; àmọ́ tó bá jẹ́ ohun tó tọ́ ni mo sọ, kí ló dé tí o fi gbá mi?” 24 Ánásì wá dè é, ó sì ní kí wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ Káyáfà àlùfáà àgbà.+

25 Símónì Pétérù wà lórí ìdúró níbẹ̀, ó ń yáná. Wọ́n wá sọ fún un pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Ó sẹ́, ó sì sọ pé: “Rárá o.”+ 26 Ọ̀kan lára àwọn ẹrú àlùfáà àgbà, tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí ọkùnrin tí Pétérù gé etí rẹ̀ dà nù+ sọ pé: “Mo rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọgbà, àbí mi ò rí ọ?” 27 Àmọ́ Pétérù tún sẹ́, àkùkọ sì kọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+

28 Wọ́n wá mú Jésù látọ̀dọ̀ Káyáfà lọ sí ilé gómìnà.+ Àárọ̀ kùtù ni. Àmọ́ àwọn fúnra wọn ò wọnú ilé gómìnà, kí wọ́n má bàa sọ ara wọn di aláìmọ́,+ kí wọ́n lè jẹ Ìrékọjá. 29 Torí náà, Pílátù jáde wá bá wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀sùn wo lẹ fi kan ọkùnrin yìí?” 30 Wọ́n dáhùn pé: “Ká ní ọkùnrin yìí ò ṣe ohun tí kò dáa ni,* a ò ní fà á lé ọ lọ́wọ́.” 31 Pílátù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ sì fi òfin yín dá a lẹ́jọ́.”+ Àwọn Júù sọ fún un pé: “Kò bófin mu fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.”+ 32 Èyí jẹ́ torí kí ọ̀rọ̀ Jésù lè ṣẹ, èyí tó sọ kí wọ́n lè mọ irú ikú tí òun máa tó kú.+

33 Torí náà, Pílátù tún wọnú ilé gómìnà, ó pe Jésù, ó sì bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù?”+ 34 Jésù dáhùn pé: “Ṣé ìwọ lo ronú ìbéèrè yìí fúnra rẹ, àbí àwọn míì ló sọ ọ̀rọ̀ mi fún ọ?” 35 Pílátù dáhùn pé: “Èmi kì í ṣe Júù, àbí Júù ni mí? Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ àti àwọn olórí àlùfáà ló fà ọ́ lé mi lọ́wọ́. Kí lo ṣe?” 36 Jésù dáhùn pé:+ “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.+ Ká ní Ìjọba mi jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ì bá ti jà kí wọ́n má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́.+ Àmọ́, bó ṣe rí yìí, Ìjọba mi ò wá láti orísun yìí.” 37 Pílátù wá bi í pé: “Ó dáa, ṣé ọba ni ọ́?” Jésù dáhùn pé: “Ìwọ fúnra rẹ ń sọ pé ọba ni mí.+ Torí èyí la ṣe bí mi, torí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.+ Gbogbo ẹni tó bá fara mọ́ òtítọ́ ń fetí sí ohùn mi.” 38 Pílátù wá bí i pé: “Kí ni òtítọ́?”

Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó tún jáde lọ bá àwọn Júù, ó sì sọ fún wọn pé: “Mi ò rí i pé ó jẹ̀bi kankan.+ 39 Àmọ́, ẹ ní àṣà kan, pé kí n máa tú ẹnì kan sílẹ̀ fún yín nígbà Ìrékọjá.+ Torí náà, ṣé ẹ fẹ́ kí n tú Ọba Àwọn Júù sílẹ̀ fún yín?” 40 Wọ́n bá tún kígbe pé: “A ò fẹ́ ọkùnrin yìí, Bárábà la fẹ́!” Àmọ́ olè ni Bárábà.+

19 Pílátù wá mú Jésù, ó sì nà án.+ 2 Àwọn ọmọ ogun fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n dé e sí i lórí, wọ́n sì wọ aṣọ aláwọ̀ pọ́pù fún un,+ 3 wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá, wọ́n sì ń sọ pé: “A kí ọ o,* ìwọ Ọba Àwọn Júù!” Wọ́n sì ń gbá a létí léraléra.+ 4 Pílátù bá tún bọ́ síta, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Mo mú un jáde wá bá yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ò rí i pé ó jẹ̀bi kankan.”+ 5 Torí náà, Jésù jáde síta, ó dé adé ẹ̀gún, ó sì wọ aṣọ aláwọ̀ pọ́pù náà. Pílátù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Ọkùnrin náà nìyí!” 6 Àmọ́, nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rí i, wọ́n kígbe pé: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”*+ Pílátù sọ fún wọn pé: “Ẹ mú un fúnra yín, kí ẹ sì pa á,* torí èmi ò rí i pé ó jẹ̀bi kankan.”+ 7 Àwọn Júù dá a lóhùn pé: “A ní òfin kan, bí òfin yẹn sì ṣe sọ, ó yẹ kó kú,+ torí ó pe ara rẹ̀ ní ọmọ Ọlọ́run.”+

8 Nígbà tí Pílátù gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, ẹ̀rù túbọ̀ bà á, 9 ló bá tún wọ ilé gómìnà, ó sì sọ fún Jésù pé: “Ibo lo ti wá?” Àmọ́ Jésù ò dá a lóhùn.+ 10 Torí náà, Pílátù sọ fún un pé: “Ṣé o ò fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀ ni? Àbí o ò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti tú ọ sílẹ̀, mo sì tún ní àṣẹ láti pa ọ́?”* 11 Jésù dá a lóhùn pé: “O ò lè ní àṣẹ kankan lórí mi àfi tí a bá fún ọ láṣẹ látòkè. Ìdí nìyẹn tí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin tó fi mí lé ọ lọ́wọ́ fi tóbi jù.”

12 Torí èyí, Pílátù ṣáà ń wá bó ṣe máa tú u sílẹ̀, àmọ́ àwọn Júù kígbe pé: “Tí o bá tú ọkùnrin yìí sílẹ̀, o kì í ṣe ọ̀rẹ́ Késárì. Ṣe ni gbogbo ẹni tó bá pe ara rẹ̀ ní ọba ń ta ko* Késárì.”+ 13 Lẹ́yìn tí Pílátù gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ó mú Jésù wá síta, ó sì jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́ níbi tí wọ́n ń pè ní Ibi Tí A Fi Òkúta Tẹ́, ìyẹn Gábátà lédè Hébérù. 14 Ó jẹ́ ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́+ Ìrékọjá; nǹkan bíi wákàtí kẹfà ni.* Ó wá sọ fún àwọn Júù pé: “Ẹ wò ó! Ọba yín nìyí!” 15 Àmọ́ wọ́n kígbe pé: “Mú un lọ! Mú un lọ! Kàn án mọ́gi!”* Pílátù sọ fún wọn pé: “Ṣé kí n pa ọba yín ni?” Àwọn olórí àlùfáà dá a lóhùn pé: “A ò ní ọba kankan àfi Késárì.” 16 Ó wá fà á lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+

Ni wọ́n bá mú Jésù lọ. 17 Ó ru òpó igi oró* náà fúnra rẹ̀, ó sì lọ síbi tí wọ́n ń pè ní Ibi Agbárí,+ ìyẹn Gọ́gọ́tà lédè Hébérù.+ 18 Ibẹ̀ ni wọ́n ti kàn án mọ́gi+ pẹ̀lú ọkùnrin méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Jésù sì wà ní àárín.+ 19 Pílátù tún kọ àkọlé kan, ó sì fi sórí òpó igi oró* náà. Ó kọ ọ́ pé: “Jésù Ará Násárẹ́tì Ọba Àwọn Júù.”+ 20 Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ka àkọlé yìí, torí pé ibi tí wọ́n ti kan Jésù mọ́gi kò jìnnà sí ìlú náà, wọ́n sì kọ ọ́ ní èdè Hébérù, èdè Látìn àti èdè Gíríìkì. 21 Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù sọ fún Pílátù pé: “Má kọ ọ́ pé, ‘Ọba Àwọn Júù,’ àmọ́ pé ó sọ pé, ‘Èmi ni Ọba Àwọn Júù.’” 22 Pílátù dáhùn pé: “Ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́.”

23 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun kan Jésù mọ́gi tán, wọ́n mú aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, wọ́n pín in sí mẹ́rin, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan, wọ́n tún mú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà ò ní ojú rírán, ṣe ni wọ́n hun ún látòkè délẹ̀. 24 Torí náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ ká ya á, àmọ́ ẹ jẹ́ ká fi kèké pinnu ti ẹni tó máa jẹ́.”+ Èyí jẹ́ torí kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ pé: “Wọ́n pín ẹ̀wù mi láàárín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ kèké nítorí aṣọ mi.”+ Àwọn ọmọ ogun náà ṣe àwọn nǹkan yìí lóòótọ́.

25 Àmọ́ ìyá+ Jésù àti arábìnrin ìyá rẹ̀ dúró sí tòsí òpó igi oró* rẹ̀; Màríà ìyàwó Kílópà àti Màríà Magidalénì.+ 26 Torí náà, nígbà tí Jésù rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ ẹ̀yìn tó nífẹ̀ẹ́,+ tí wọ́n dúró nítòsí, ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Obìnrin, wò ó! Ọmọ rẹ!” 27 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ọmọ ẹ̀yìn náà pé: “Wò ó! Ìyá rẹ!” Láti wákàtí yẹn lọ, ọmọ ẹ̀yìn náà mú un lọ sí ilé ara rẹ̀.

28 Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù mọ̀ pé a ti ṣe ohun gbogbo parí, kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ, ó sọ pé: “Òùngbẹ ń gbẹ mí.”+ 29 Ìṣà kan wà níbẹ̀ tí wáìnì kíkan kún inú rẹ̀. Torí náà, wọ́n fi kànrìnkàn tí wọ́n rẹ sínú wáìnì kíkan sórí pòròpórò hísópù,* wọ́n sì gbé e sí i lẹ́nu.+ 30 Lẹ́yìn tó gba wáìnì kíkan náà, Jésù sọ pé: “A ti ṣe é parí!”+ ló bá tẹ orí rẹ̀ ba, ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.*+

31 Torí pé ó jẹ́ ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́,+ àwọn Júù ní kí Pílátù ṣẹ́ ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n sì gbé òkú wọn lọ, kí àwọn òkú náà má bàa wà lórí òpó igi oró+ ní Sábáàtì (torí pé ọjọ́ ńlá ni Sábáàtì yẹn).+ 32 Torí náà, àwọn ọmọ ogun wá, wọ́n sì ṣẹ́ ẹsẹ̀ ọkùnrin àkọ́kọ́ àti ti ọkùnrin kejì tó wà lórí òpó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. 33 Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n rí i pé ó ti kú, torí náà, wọn ò ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. 34 Ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́,+ ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 35 Ẹni tó rí i ti jẹ́rìí yìí, òótọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀, ó sì mọ̀ pé òótọ́ ni ohun tí òun sọ, kí ẹ̀yin náà lè gbà gbọ́.+ 36 Ní tòótọ́, àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ pé: “Wọn ò ní ṣẹ́* ìkankan nínú egungun rẹ̀.”+ 37 Ẹsẹ ìwé mímọ́ míì tún sọ pé: “Wọ́n máa wo ẹni tí wọ́n gún.”+

38 Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, Jósẹ́fù ará Arimatíà, tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àmọ́ tí kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí pé ó ń bẹ̀rù àwọn Júù,+ béèrè lọ́wọ́ Pílátù pé kó jẹ́ kí òun gbé òkú Jésù lọ, Pílátù sì gbà á láyè. Torí náà, ó wá gbé òkú rẹ̀ lọ.+ 39 Nikodémù+ náà wá, ọkùnrin tó ti kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní òru, ó mú àdàpọ̀* òjíá àti álóé wá, ó tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún (100) ìwọ̀n pọ́n-ùn.*+ 40 Torí náà, wọ́n gbé òkú Jésù, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀* dì í pẹ̀lú àwọn èròjà tó ń ta sánsán náà,+ bí àwọn Júù ṣe máa ń sìnkú. 41 Ó ṣẹlẹ̀ pé ọgbà kan wà níbi tí wọ́n ti pa á,* ibojì* tuntun+ kan sì wà nínú ọgbà náà, tí wọn ò tẹ́ ẹnì kankan sí rí. 42 Torí pé ó jẹ́ ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́ + àwọn Júù, tí ibojì náà sì wà nítòsí, wọ́n tẹ́ Jésù síbẹ̀.

20 Ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, Màríà Magidalénì wá síbi ibojì* náà ní àárọ̀ kùtù,+ nígbà tí ilẹ̀ ò tíì mọ́, ó sì rí i pé wọ́n ti gbé òkúta náà kúrò níbi ibojì* náà.+ 2 Ló bá sáré wá bá Símónì Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn kejì, ẹni tí Jésù nífẹ̀ẹ́ gan-an,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì,+ a ò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”

3 Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn kejì wá gbéra lọ síbi ibojì náà. 4 Àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ sáré, àmọ́ ọmọ ẹ̀yìn kejì yára ju Pétérù lọ, òun ló sì kọ́kọ́ dé ibojì náà. 5 Ó wá bẹ̀rẹ̀ wo iwájú, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀* nílẹ̀ níbẹ̀,+ àmọ́ kò wọlé. 6 Símónì Pétérù náà dé lẹ́yìn rẹ̀, ó sì wọnú ibojì náà. Ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ nílẹ̀ níbẹ̀. 7 Aṣọ tó wà ní orí rẹ̀ kò sí níbi tí aṣọ yòókù tí wọ́n fi dì í wà, àmọ́ ó dá wà níbì kan, ní kíká jọ. 8 Ọmọ ẹ̀yìn kejì tó kọ́kọ́ dé ibojì náà wá wọlé, ó rí i, ó sì gbà gbọ́. 9 Torí ìwé mímọ́ ò tíì yé wọn pé ó gbọ́dọ̀ jíǹde.+ 10 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà pa dà sí ilé wọn.

11 Àmọ́ Màríà ò kúrò níbi tó dúró sí níta nítòsí ibojì náà, ó ń sunkún. Bó ṣe ń sunkún, ó bẹ̀rẹ̀ wo inú ibojì náà, 12 ó sì rí áńgẹ́lì méjì+ tó wọ aṣọ funfun tí wọ́n jókòó síbi tí wọ́n tẹ́ Jésù sí tẹ́lẹ̀, ọ̀kan níbi orí, ọ̀kan níbi ẹsẹ̀. 13 Wọ́n sọ fún un pé: “Obìnrin yìí, kí ló dé tó ò ń sunkún?” Ó sọ fún wọn pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa mi lọ, mi ò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” 14 Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó yíjú pa dà, ó sì rí Jésù tó dúró síbẹ̀, àmọ́ kò mọ̀ pé Jésù ni.+ 15 Jésù sọ fún un pé: “Obìnrin yìí, kí ló dé tí o fi ń sunkún? Ta lò ń wá?” Obìnrin náà rò pé ẹni tó ń tọ́jú ọgbà ni, ló bá sọ fún un pé: “Ọ̀gá, tó bá jẹ́ ìwọ lo gbé e kúrò, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, màá sì gbé e lọ.” 16 Jésù sọ fún un pé: “Màríà!” Ló bá yíjú pa dà, ó sì sọ fún un ní èdè Hébérù pé: “Rábónì!” (tó túmọ̀ sí “Olùkọ́!”) 17 Jésù sọ fún un pé: “Má rọ̀ mọ́ mi mọ́, torí mi ò tíì gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba. Àmọ́ lọ bá àwọn arákùnrin mi,+ kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi+ àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi+ àti Ọlọ́run yín.’” 18 Màríà Magidalénì wá ròyìn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Mo ti rí Olúwa!” Ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó sọ fún òun.+

19 Nígbà tí ọjọ́ ti lọ lọ́jọ́ yẹn, ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, tí ilẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn wà sì wà ní títì pa torí pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn Júù, Jésù wá, ó dúró ní àárín wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.”+ 20 Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó fi ọwọ́ rẹ̀ àti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀+ hàn wọ́n. Inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì dùn pé wọ́n rí Olúwa.+ 21 Jésù tún sọ fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.+ Bí Baba ṣe rán mi gẹ́lẹ́+ ni èmi náà ń rán yín.”+ 22 Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó fẹ́ atẹ́gùn sí wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ gba ẹ̀mí mímọ́.+ 23 Tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ẹnikẹ́ni, wọ́n á rí ìdáríjì; tí ẹ bá ní kí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni ṣì wà, wọ́n ṣì máa wà.”

24 Àmọ́ Tọ́másì,+ ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà, tí wọ́n ń pè ní Ìbejì, kò sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí Jésù wá. 25 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù ń sọ fún un pé: “A ti rí Olúwa!” Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Láìjẹ́ pé mo rí àpá* ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀, tí mo ki ìka mi bọ àpá ìṣó náà, tí mo sì ki ọwọ́ mi bọ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,+ mi ò ní gbà gbọ́ láé.”

26 Ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tún wà nínú ilé, Tọ́másì sì wà pẹ̀lú wọn. Jésù wá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ilẹ̀kùn pa, ó dúró ní àárín wọn, ó sì sọ pé: “Àlàáfíà fún yín o.”+ 27 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Tọ́másì pé: “Fi ìka rẹ síbí, kí o sì wo ọwọ́ mi, ki ọwọ́ rẹ bọ ẹ̀gbẹ́ mi, kí o má sì ṣiyèméjì* mọ́, àmọ́ kí o gbà gbọ́.” 28 Tọ́másì dá a lóhùn pé: “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!” 29 Jésù sọ fún un pé: “Ṣé o ti wá gbà gbọ́ torí pé o rí mi? Aláyọ̀ ni àwọn tí kò rí, síbẹ̀ tí wọ́n gbà gbọ́.”

30 Ó dájú pé Jésù tún ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì míì níṣojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn, tí a ò kọ sínú àkájọ ìwé yìí.+ 31 Àmọ́ a kọ àwọn yìí sílẹ̀ kí ẹ lè gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, kí ẹ sì lè ní ìyè nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀ tí ẹ bá gbà gbọ́.+

21 Lẹ́yìn èyí, Jésù tún fara han* àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní òkun Tìbéríà. Bó ṣe fara hàn wọ́n nìyí. 2 Símónì Pétérù, Tọ́másì (tí wọ́n ń pè ní Ìbejì),+ Nàtáníẹ́lì+ láti Kánà ti Gálílì, àwọn ọmọ Sébédè+ àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì míì jọ wà níbì kan náà. 3 Símónì Pétérù sọ fún wọn pé: “Mò ń lọ pẹja.” Wọ́n sọ fún un pé: “A máa tẹ̀ lé ọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọnú ọkọ̀ ojú omi, àmọ́ wọn ò rí nǹkan kan mú ní òru yẹn.+

4 Àmọ́ bí ilẹ̀ ṣe ń mọ́ bọ̀, Jésù dúró sí etíkun, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn ò mọ̀ pé Jésù ni.+ 5 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ ò ní nǹkan* tí ẹ máa jẹ, àbí ẹ ní?” Wọ́n dáhùn pé: “Rárá o!” 6 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ju àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ sì máa rí díẹ̀.” Torí náà, wọ́n jù ú, àmọ́ wọn ò lè fà á wọlé torí ẹja tí wọ́n kó pọ̀.+ 7 Ni ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù nífẹ̀ẹ́+ bá sọ fún Pétérù pé: “Olúwa ni!” Bí Símónì Pétérù ṣe gbọ́ pé Olúwa ni, ó wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,* torí pé ìhòòhò ló wà,* ó sì bẹ́ sínú òkun. 8 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù wọ ọkọ̀ ojú omi kékeré náà wá, wọ́n ń fa àwọ̀n tí ẹja kún inú rẹ̀, torí pé wọn ò jìnnà sí ilẹ̀, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ẹsẹ̀ bàtà* péré ni sórí ilẹ̀.

9 Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹja lórí iná èédú níbẹ̀, wọ́n sì rí búrẹ́dì. 10 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ mú díẹ̀ wá lára ẹja tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa.” 11 Torí náà, Símónì Pétérù wọnú ọkọ̀, ó sì fa àwọ̀n tí ẹja ńlá kún inú rẹ̀ wá sórí ilẹ̀, ọgọ́rùn-ún kan àti mẹ́tàléláàádọ́ta (153) làwọn ẹja náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó pọ̀ gan-an, àwọ̀n náà ò ya. 12 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ wá jẹ oúnjẹ àárọ̀.” Ìkankan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ò nígboyà láti bi í pé: “Ta ni ọ́?” torí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni. 13 Jésù wá, ó mú búrẹ́dì náà, ó sì fún wọn, ó ṣe bẹ́ẹ̀ náà sí ẹja. 14 Ìgbà kẹta nìyí+ tí Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́yìn tó jíǹde.

15 Lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ àárọ̀ tán, Jésù sọ fún Símónì Pétérù pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ?” Ó sọ fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, o mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọ.” Ó sọ fún un pé: “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn mi.”+ 16 Ó tún sọ fún un lẹ́ẹ̀kejì pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o nífẹ̀ẹ́ mi?” Ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, o mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọ.” Ó sọ fún un pé: “Máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.”+ 17 Ó sọ fún un lẹ́ẹ̀kẹta pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi?” Ẹ̀dùn ọkàn bá Pétérù torí ó bi í lẹ́ẹ̀kẹta pé: “Ṣé o ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi?” Torí náà, ó sọ fún un pé: “Olúwa, o mọ ohun gbogbo; o mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọ.” Jésù sọ fún un pé: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.+ 18 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, nígbà tí o wà ní ọ̀dọ́, o máa ń wọ aṣọ fúnra rẹ, o sì máa ń rìn káàkiri lọ síbi tí o fẹ́. Àmọ́ tí o bá darúgbó, o máa na ọwọ́ rẹ, ẹlòmíì máa wọ aṣọ fún ọ, ó sì máa gbé ọ lọ síbi tó ò fẹ́.” 19 Ó sọ èyí láti fi tọ́ka sí irú ikú tó máa fi yin Ọlọ́run lógo. Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.”+

20 Pétérù yíjú pa dà, ó sì rí ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù nífẹ̀ẹ́+ tó ń tẹ̀ lé e, òun ló fẹ̀yìn ti àyà rẹ̀ níbi oúnjẹ alẹ́, tó sì sọ pé: “Olúwa, ta ló máa dà ọ́?” 21 Torí náà, nígbà tó tajú kán rí i, Pétérù sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ẹni yìí ńkọ́?” 22 Jésù sọ fún un pé: “Kí ló kàn ọ́ tí mo bá fẹ́ kó wà títí màá fi dé? Ìwọ ṣáà máa tẹ̀ lé mi.” 23 Torí náà, ọ̀rọ̀ yìí tàn kálẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin pé ọmọ ẹ̀yìn yẹn ò ní kú. Àmọ́, Jésù ò sọ fún un pé kò ní kú, ohun tó sọ ni pé: “Kí ló kàn ọ́ tí mo bá fẹ́ kó wà títí màá fi dé?”

24 Ọmọ ẹ̀yìn yìí+ ló jẹ́rìí yìí nípa àwọn nǹkan yìí, tó sì kọ àwọn nǹkan yìí, a sì mọ̀ pé òótọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀.

25 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan míì wà tí Jésù ṣe, tó jẹ́ pé, tí a bá kọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn, mo wò ó pé, ayé pàápàá ò ní lè gba àwọn àkájọ ìwé tí a bá kọ ọ́ sí.+

Tàbí “jẹ́ ẹni ti ọ̀run.”

Tàbí “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.”

Tàbí “ní oókan àyà Baba.” Ipò ojúure àrà ọ̀tọ̀ ni èyí ń tọ́ka sí.

Wo Àfikún A5.

Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́.

Ní Grk., “Kí ló pa èmi àti ìwọ pọ̀, obìnrin?” Àkànlò èdè tí èèyàn fi ń sọ pé òun ò fara mọ́ nǹkan nìyí. Bó ṣe pè é ní “obìnrin” kò túmọ̀ sí pé kò bọ̀wọ̀ fún un.

Ó ṣeé ṣe kí òṣùwọ̀n nǹkan olómi náà jẹ́ báàtì tó jẹ́ Lítà 22 (gálọ́ọ̀nù 5.81). Wo Àfikún B14.

Tàbí “ọjà; ibi ìṣòwò.”

Tàbí kó jẹ́, “bí ẹnikẹ́ni láti òkè.”

Tàbí “tú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ fó.”

Tàbí “rí i dájú pé.”

Tàbí “kì í díwọ̀n ẹ̀mí fúnni.”

Tàbí “orísun omi; ìsun omi.”

Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.

Tàbí “pé ara ọmọ rẹ̀ ti ń yá.”

Ìyẹn, nǹkan bí aago kan ọ̀sán.

Tàbí “ìloro.”

Wo Àfikún A3.

Tàbí “ibùsùn.”

Tàbí “ibùsùn.”

Tàbí “ibùsùn.”

Tàbí “ibùsùn.”

Tàbí “ṣe ní ẹ̀bùn ìwàláàyè nínú ara rẹ̀.”

Ìyẹn, Ìwé Mímọ́.

Wo Àfikún B14.

Nǹkan bíi kìlómítà márùn-ún sí mẹ́fà. Ní Grk., “nǹkan bíi sítédíọ̀mù 25 sí 30.” Wo Àfikún B14.

Wo Àfikún A5.

Tàbí kó jẹ́, “níbi táwọn èèyàn pé jọ sí.”

Tàbí “èṣù.”

Tàbí “rìn káàkiri.”

Tàbí “Àwọn Àtíbàbà.”

Ní Grk., “àwọn àkọsílẹ̀.”

Ìyẹn, ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì.

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “fàṣẹ ọba mú un.”

Tàbí “fàṣẹ ọba mú un.”

Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ kan tó ṣeé gbára lé kò fi ẹsẹ 53 sí orí 8, ẹsẹ 11 kún un.

Tàbí “lọ́nà ti èèyàn.”

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “láti ìbẹ̀rẹ̀.”

Tàbí “forí balẹ̀.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ìloro.”

Tàbí “ọkàn wa.”

Tàbí “wà ní ìṣọ̀kan.”

Tàbí “ẹni bí Ọlọ́run.”

Tàbí “ibojì ìrántí.”

Nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ta. Ní Grk., “nǹkan bíi sítédíọ̀mù 15.” Wo Àfikún B14.

Tàbí “ibojì ìrántí.”

Ní Grk., “bá a nínú ẹ̀mí.”

Tàbí “ibojì ìrántí.”

Ìyẹn, tẹ́ńpìlì.

Tàbí “fàṣẹ ọba mú un.”

Tàbí “rọ̀gbọ̀kú sídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀.”

Ìyẹn, pọ́n-ùn ti àwọn ará Róòmù, nǹkan bíi gíráàmù 327. Wo Àfikún B14.

Wo Àfikún B14.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “agódóńgbó.”

Tàbí “ibojì ìrántí.”

Tàbí “wíìtì.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “nínú ìròyìn wa?”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “di ara rẹ̀ lámùrè.”

Tàbí “tó fi di ara rẹ̀ lámùrè.”

Ní Grk., “rọ̀gbọ̀kú.”

Tàbí “ó di dandan.”

Tàbí “ti yíjú pa dà sí mi.”

Ní Grk., “rọ̀gbọ̀kú.”

Ní Grk., “ní oókan àyà.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọ̀pọ̀ ibùjókòó.”

Tàbí “olùtùnú.”

Tàbí “bí àwọn ọmọ aláìlóbìí.”

Tàbí “ibùjókòó.”

Tàbí “kò sì ní àṣẹ kankan lórí mi.”

Tàbí “ọkàn.”

Ọ̀rọ̀ náà “ìyẹn” àti “ó” tó wà ní ẹsẹ 13 àti 14 ń tọ́ka sí “olùrànlọ́wọ́” tó wà ní ẹsẹ 7. Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “olùrànlọ́wọ́” (tí wọ́n ń lò fún ọkùnrin lédè Gíríìkì) bí àkànlò èdè tó ń tọ́ka sí ẹ̀mí mímọ́ bíi pé ó jẹ́ ẹnì kan. Agbára ni ẹ̀mí yìí, kì í ṣe ẹnì kan, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún un lédè Gíríìkì kò tọ́ka sí ọkùnrin tàbí obìnrin.

Tàbí “aráyé; èèyàn.”

Tàbí “kí wọ́n gba ìmọ̀ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo sínú.”

Tàbí “Mo ti jẹ́ kí àwọn èèyàn tí o fún mi látinú ayé mọ orúkọ rẹ.”

Tàbí “ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.”

Tàbí “wà ní ìṣọ̀kan.”

Tàbí “wà ní ìṣọ̀kan.”

Tàbí “Yà wọ́n sọ́tọ̀; Jẹ́ kí wọ́n di mímọ́.”

Tàbí “kí a lè mú kí wọ́n ṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀.”

Tàbí “ojú ọ̀gbàrá Kídírónì ti ìgbà òtútù.”

Tàbí “fàṣẹ ọba mú.”

Tàbí “àbáwọlé.”

Tàbí “jẹ́rìí sí.”

Tàbí “kì í ṣe ọ̀daràn ni.”

Tàbí “A júbà rẹ.”

Tàbí “mọ́ òpó igi!” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “kàn án mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “kàn ọ́ mọ́ òpó igi?” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “sọ̀rọ̀ òdì sí.”

Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.

Tàbí “mọ́ òpó igi!” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ó sì gbẹ́mìí mì.”

Tàbí “fọ́.”

Tàbí kó jẹ́, “àdìpọ̀.”

Ìyẹn, pọ́n-ùn ti àwọn ará Róòmù. Wo Àfikún B14.

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “kàn án mọ́gi.”

Tàbí “ibojì ìrántí.”

Tàbí “ibojì ìrántí.”

Tàbí “ibojì ìrántí.”

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “àmì.”

Ní Grk., “jẹ́ aláìnígbàgbọ́.”

Tàbí “fi ara rẹ̀ hàn kedere fún.”

Tàbí “ẹja kankan.”

Tàbí “fi aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ di ara rẹ̀ lámùrè.”

Tàbí “aṣọ jáńpé ló wà lára rẹ̀.”

Nǹkan bíi 90 mítà. Ní Grk., “nǹkan bíi 200 ìgbọ̀nwọ́.” Wo Àfikún B14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́