KÍRÓNÍKÀ KÌÍNÍ
5 Àwọn ọmọ Jáfẹ́tì ni Gómérì, Mágọ́gù, Mádáì, Jáfánì, Túbálì,+ Méṣékì+ àti Tírásì.+
6 Àwọn ọmọ Gómérì ni Áṣíkénásì, Rífátì àti Tógámà.+
7 Àwọn ọmọ Jáfánì ni Élíṣáhì, Táṣíṣì, Kítímù àti Ródánímù.
8 Àwọn ọmọ Hámù ni Kúṣì,+ Mísíráímù, Pútì àti Kénáánì.+
9 Àwọn ọmọ Kúṣì ni Sébà,+ Háfílà, Sábítà, Ráámà+ àti Sábítékà.
Àwọn ọmọ Ráámà sì ni Ṣébà àti Dédánì.+
10 Kúṣì bí Nímírọ́dù.+ Òun ló kọ́kọ́ di alágbára ní ayé.
11 Mísíráímù bí Lúdímù,+ Ánámímù, Léhábímù, Náfútúhímù,+ 12 Pátírúsímù,+ Kásílúhímù (ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àwọn Filísínì+ ti wá) àti Káfítórímù.+
13 Kénáánì bí Sídónì+ àkọ́bí rẹ̀ àti Hétì+ 14 àti àwọn ará Jébúsì,+ àwọn Ámórì,+ àwọn Gẹ́gáṣì,+ 15 àwọn Hífì,+ àwọn Ákì, àwọn Sáínì, 16 àwọn ọmọ Áfádì,+ àwọn Sémárì àti àwọn ará Hámátì.
18 Ápákíṣádì bí Ṣélà, Ṣélà+ sì bí Ébérì.
19 Ọmọ méjì ni Ébérì bí. Ọ̀kan ń jẹ́ Pélégì,*+ torí pé ìgbà ayé rẹ̀ ni ayé* pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jókítánì.
20 Jókítánì bí Álímódádì, Ṣéléfì, Hasamáfétì, Jérà,+ 21 Hádórámù, Úsálì, Díkílà, 22 Óbálì, Ábímáélì, Ṣébà, 23 Ófírì,+ Háfílà+ àti Jóbábù; gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Jókítánì.
28 Àwọn ọmọ Ábúráhámù ni Ísákì+ àti Íṣímáẹ́lì.+
29 Ibi tí ìdílé wọn ti wá nìyí: Àkọ́bí Íṣímáẹ́lì ni Nébáótì,+ lẹ́yìn náà ó bí Kídárì,+ Ádíbéélì, Míbúsámù,+ 30 Míṣímà, Dúmà, Máásà, Hádádì, Témà, 31 Jétúrì, Náfíṣì àti Kédémà. Àwọn yìí ni ọmọ Íṣímáẹ́lì.
32 Àwọn ọmọ tí Kétúrà,+ wáhàrì* Ábúráhámù bí ni Símíránì, Jókíṣánì, Médánì, Mídíánì,+ Íṣíbákì àti Ṣúáhì.+
Àwọn ọmọ Jókíṣánì ni Ṣébà àti Dédánì.+
33 Àwọn ọmọ Mídíánì ni Eéfà,+ Éférì, Hánókù, Ábíídà àti Élídáà.
Ọmọ Kétúrà ni gbogbo wọn.
34 Ábúráhámù bí Ísákì. Àwọn ọmọ Ísákì+ ni Ísọ̀+ àti Ísírẹ́lì.+
35 Àwọn ọmọ Ísọ̀ ni Élífásì, Réúẹ́lì, Jéúṣì, Jálámù àti Kórà.+
36 Àwọn ọmọ Élífásì ni Témánì,+ Ómárì, Séfò, Gátámù, Kénásì, Tímínà àti Ámálékì.+
37 Àwọn ọmọ Réúẹ́lì ni Náhátì, Síírà, Ṣámà àti Mísà.+
38 Àwọn ọmọ Séírì+ ni Lótánì, Ṣóbálì, Síbéónì, Ánáhì, Díṣónì, Ésérì àti Díṣánì.+
39 Àwọn ọmọ Lótánì ni Hórì àti Hómámù. Arábìnrin Lótánì sì ni Tímínà.+
40 Àwọn ọmọ Ṣóbálì ni Álífánì, Mánáhátì, Ébálì, Ṣéfò àti Ónámù.
Àwọn ọmọ Síbéónì sì ni Áyà àti Ánáhì.+
41 Ọmọ* Ánáhì ni Díṣónì.
Àwọn ọmọ Díṣónì sì ni Hémúdánì, Éṣíbánì, Ítíránì àti Kéránì.+
42 Àwọn ọmọ Ésérì+ ni Bílíhánì, Sááfánì àti Ékánì.
Àwọn ọmọ Díṣánì ni Úsì àti Áránì.+
43 Àwọn ọba tó jẹ ní ilẹ̀ Édómù+ kí ọba kankan tó jẹ lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ nìyí: Bélà ọmọ Béórì; orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dínhábà. 44 Nígbà tí Bélà kú, Jóbábù ọmọ Síírà láti Bósírà+ bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 45 Nígbà tí Jóbábù kú, Húṣámù láti ilẹ̀ àwọn ará Témánì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 46 Nígbà tí Húṣámù kú, Hádádì ọmọ Bédádì, ẹni tó ṣẹ́gun Mídíánì ní agbègbè* Móábù bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Áfítì. 47 Nígbà tí Hádádì kú, Sámúlà láti Másírékà bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 48 Nígbà tí Sámúlà kú, Ṣéọ́lù láti Réhóbótì lẹ́gbẹ̀ẹ́ Odò bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 49 Nígbà tí Ṣéọ́lù kú, Baali-hánánì ọmọ Ákíbórì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 50 Nígbà tí Baali-hánánì kú, Hádádì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Páù, orúkọ ìyàwó rẹ̀ sì ni Méhétábélì ọmọ Mátírédì, ọmọbìnrin Mésáhábù. 51 Lẹ́yìn náà, Hádádì kú.
Àwọn séríkí* Édómù ni Séríkí Tímínà, Séríkí Álíífà, Séríkí Jététì,+ 52 Séríkí Oholibámà, Séríkí Élà, Séríkí Pínónì, 53 Séríkí Kénásì, Séríkí Témánì, Séríkí Míbúsárì, 54 Séríkí Mágídíélì, Séríkí Írámù. Àwọn yìí ni séríkí Édómù.
2 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ nìyí: Rúbẹ́nì,+ Síméónì,+ Léfì,+ Júdà,+ Ísákà,+ Sébúlúnì,+ 2 Dánì,+ Jósẹ́fù,+ Bẹ́ńjámínì,+ Náfútálì,+ Gádì+ àti Áṣérì.+
3 Àwọn ọmọ Júdà ni Éérì, Ónánì àti Ṣélà. Àwọn mẹ́ta yìí ni ọmọbìnrin Ṣúà ará Kénáánì+ bí fún un. Àmọ́, inú Jèhófà ò dùn sí Éérì àkọ́bí Júdà, torí náà Ó pa á.+ 4 Támárì+ ìyàwó ọmọ Júdà bí Pérésì+ àti Síírà fún un. Gbogbo àwọn ọmọ Júdà jẹ́ márùn-ún.
5 Àwọn ọmọ Pérésì ni Hésírónì àti Hámúlù.+
6 Àwọn ọmọ Síírà ni Símírì, Étánì, Hémánì, Kálíkólì àti Dárà. Gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.
7 Ọmọ* Kámì ni Ákárì,* ẹni tó mú àjálù* bá Ísírẹ́lì+ nígbà tó hùwà àìṣòótọ́ torí ó mú ohun tí wọ́n fẹ́ pa run.+
8 Ọmọ* Étánì ni Asaráyà.
9 Àwọn ọmọ Hésírónì ni Jéráméélì,+ Rámù+ àti Kélúbáì.*
10 Rámù bí Ámínádábù. Ámínádábù+ bí Náṣónì,+ ìjòyè àwọn ọmọ Júdà. 11 Náṣónì bí Sálímà.+ Sálímà bí Bóásì.+ 12 Bóásì bí Óbédì. Óbédì bí Jésè.+ 13 Jésè bí àkọ́bí rẹ̀ Élíábù, ìkejì Ábínádábù,+ ìkẹta Ṣíméà,+ 14 ìkẹrin Nétánélì, ìkarùn-ún Rádáì, 15 ìkẹfà Ósémù àti ìkeje Dáfídì.+ 16 Àwọn arábìnrin wọn ni Seruáyà àti Ábígẹ́lì.+ Àwọn ọmọ Seruáyà ni Ábíṣáì,+ Jóábù+ àti Ásáhélì,+ àwọn mẹ́ta. 17 Ábígẹ́lì bí Ámásà,+ bàbá Ámásà sì ni Jétà ọmọ Íṣímáẹ́lì.
18 Ásúbà ìyàwó Kélẹ́bù* ọmọ Hésírónì bí àwọn ọmọ fún un, Jéríótì tún bímọ fún un; àwọn ọmọ rẹ̀ ni: Jéṣà, Ṣóbábù àti Árídónì. 19 Nígbà tí Ásúbà kú, Kélẹ́bù fẹ́ Éfúrátì,+ ó sì bí Húrì+ fún un. 20 Húrì bí Úráì. Úráì bí Bẹ́sálẹ́lì.+
21 Lẹ́yìn náà, Hésírónì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Mákírù+ bàbá Gílíádì,+ ó sì bí Ségúbù fún un. Ẹni ọgọ́ta (60) ọdún ni Hésírónì nígbà tí ó fẹ́ ẹ. 22 Ségúbù bí Jáírì,+ ẹni tó ní ìlú mẹ́tàlélógún (23) ní ilẹ̀ Gílíádì.+ 23 Lẹ́yìn náà, Géṣúrì+ àti Síríà+ gba Hafotu-jáírì+ lọ́wọ́ wọn, pẹ̀lú Kénátì+ àti àwọn àrọko rẹ̀,* ọgọ́ta (60) ìlú. Gbogbo àwọn yìí ni àtọmọdọ́mọ Mákírù bàbá Gílíádì.
24 Lẹ́yìn tí Hésírónì+ kú ní Kelẹbu-éfúrátà, Ábíjà ìyàwó Hésírónì bí Áṣíhúrì+ bàbá Tékóà+ fún un.
25 Àwọn ọmọ Jéráméélì àkọ́bí Hésírónì ni Rámù àkọ́bí, Búnà, Órénì, Ósémù àti Áhíjà. 26 Jéráméélì ní ìyàwó míì, orúkọ rẹ̀ ni Átárà. Òun ni ìyá Ónámù. 27 Àwọn ọmọ Rámù àkọ́bí Jéráméélì ni Máásì, Jámínì àti Ékérì. 28 Àwọn ọmọ Ónámù ni Ṣámáì àti Jádà. Àwọn ọmọ Ṣámáì ni Nádábù àti Ábíṣúrì. 29 Orúkọ ìyàwó Ábíṣúrì ni Ábíháílì, òun ló bí Ábánì àti Mólídì fún un. 30 Àwọn ọmọ Nádábù ni Sélédì àti Ápáímù. Àmọ́ Sélédì kú láìní ọmọ. 31 Ọmọ* Ápáímù ni Íṣì. Ọmọ* Íṣì ni Ṣéṣánì, ọmọ* Ṣéṣánì sì ni Áláì. 32 Àwọn ọmọ Jádà àbúrò Ṣámáì ni Jétà àti Jónátánì. Àmọ́, Jétà kú láìní ọmọ. 33 Àwọn ọmọ Jónátánì ni Péléétì àti Sásà. Àwọn yìí ni àtọmọdọ́mọ Jéráméélì.
34 Ṣéṣánì kò ní ọmọkùnrin kankan, àfi àwọn ọmọbìnrin. Ṣéṣánì ní ìránṣẹ́ kan tó jẹ́ ará Íjíbítì, Jááhà ni orúkọ rẹ̀. 35 Ṣéṣánì wá fún Jááhà ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọmọbìnrin rẹ̀ pé kó fi ṣe aya, ó sì bí Átáì fún un. 36 Átáì bí Nátánì. Nátánì bí Sábádì. 37 Sábádì bí Éfílálì. Éfílálì bí Óbédì. 38 Óbédì bí Jéhù. Jéhù bí Asaráyà. 39 Asaráyà bí Hélésì. Hélésì bí Éléásà. 40 Éléásà bí Sísímáì. Sísímáì bí Ṣálúmù. 41 Ṣálúmù bí Jekamáyà. Jekamáyà bí Élíṣámà.
42 Àwọn ọmọ Kélẹ́bù*+ àbúrò Jéráméélì ni Méṣà àkọ́bí rẹ̀ tí ó jẹ́ bàbá Sífù àti àwọn ọmọ Máréṣà bàbá Hébúrónì. 43 Àwọn ọmọ Hébúrónì ni Kórà, Tápúà, Rékémù àti Ṣímà. 44 Ṣímà bí Ráhámù bàbá Jọ́kéámù. Rékémù bí Ṣámáì. 45 Ọmọ Ṣámáì ni Máónì. Máónì sì ni bàbá Bẹti-súrì.+ 46 Eéfà wáhàrì* Kélẹ́bù bí Háránì, Mósà àti Gásésì. Háránì bí Gásésì. 47 Àwọn ọmọ Jáádáì ni Régémù, Jótámù, Géṣánì, Pélétì, Eéfà àti Ṣááfà. 48 Máákà wáhàrì Kélẹ́bù bí Ṣébérì àti Tíhánà. 49 Nígbà tó yá, ó bí Ṣááfà bàbá Mádímánà+ àti Ṣéfà bàbá Mákíbénà pẹ̀lú Gíbéà.+ Ọmọbìnrin Kélẹ́bù+ sì ni Ákúsà.+ 50 Àwọn yìí ni àtọmọdọ́mọ Kélẹ́bù.
Àwọn ọmọ Húrì+ àkọ́bí Éfúrátà+ ni Ṣóbálì bàbá Kiriati-jéárímù,+ 51 Sálímà bàbá Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ àti Háréfì bàbá Bẹti-gádérì. 52 Ṣóbálì bàbá Kiriati-jéárímù ní àwọn ọmọ, àwọn ni: Háróè àti ìdajì àwọn Mẹ́núhótì. 53 Àwọn ìdílé Kiriati-jéárímù ni àwọn Ítírì,+ àwọn Púútì, àwọn Ṣúmátì àti àwọn Míṣíráì. Inú àwọn yìí ni àwọn Sórátì+ àti àwọn ará Éṣítáólì+ ti wá. 54 Àwọn ọmọ Sálímà ni Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ àwọn ará Nétófà, Atiroti-bẹti-jóábù, ìdajì àwọn ọmọ Mánáhátì àti àwọn Sórítì. 55 Ìdílé àwọn akọ̀wé òfin tó ń gbé ní Jábésì ni àwọn Tírátì, àwọn Ṣímíátì àti àwọn Súkátì. Àwọn yìí ni àwọn Kénì+ tó wá látọ̀dọ̀ Hémátì bàbá ilé Rékábù.+
3 Àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n bí fún Dáfídì ní Hébúrónì+ nìyí: Ámínónì+ àkọ́bí, ìyá rẹ̀ ni Áhínóámù+ ará Jésírẹ́lì; ìkejì ni Dáníẹ́lì, ìyá rẹ̀ ni Ábígẹ́lì+ ará Kámẹ́lì; 2 ìkẹta ni Ábúsálómù+ ọmọ Máákà ọmọbìnrin Tálímáì ọba Géṣúrì; ìkẹrin ni Ádóníjà+ ọmọ Hágítì; 3 ìkarùn-ún ni Ṣẹfatáyà, ìyá rẹ̀ ni Ábítálì; ìkẹfà sì ni Ítíréámù, ìyá rẹ̀ ní Ẹ́gílà ìyàwó Dáfídì. 4 Àwọn mẹ́fà yìí ni wọ́n bí fún un ní Hébúrónì; ọdún méje àti oṣù mẹ́fà ló fi jọba níbẹ̀, ó sì fi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) jọba ní Jerúsálẹ́mù.+
5 Àwọn tí wọ́n bí fún un ní Jerúsálẹ́mù+ nìyí: Ṣíméà, Ṣóbábù, Nátánì+ àti Sólómọ́nì;+ ìyá àwọn mẹ́rin yìí ni Bátí-ṣébà+ ọmọbìnrin Ámíélì. 6 Àwọn ọmọ mẹ́sàn-án míì ni Íbárì, Élíṣámà, Élífélétì, 7 Nógà, Néfégì, Jáfíà, 8 Élíṣámà, Élíádà àti Élífélétì. 9 Gbogbo àwọn yìí ni ọmọ Dáfídì, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ àwọn wáhàrì,* Támárì+ sì ni arábìnrin wọn.
10 Ọmọ Sólómọ́nì ni Rèhóbóámù;+ ọmọ* rẹ̀ ni Ábíjà,+ ọmọ rẹ̀ ni Ásà,+ ọmọ rẹ̀ ni Jèhóṣáfátì,+ 11 ọmọ rẹ̀ ni Jèhórámù,+ ọmọ rẹ̀ ni Ahasáyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Jèhóáṣì,+ 12 ọmọ rẹ̀ ni Amasááyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Asaráyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Jótámù,+ 13 ọmọ rẹ̀ ni Áhásì,+ ọmọ rẹ̀ ni Hẹsikáyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Mánásè,+ 14 ọmọ rẹ̀ ni Ámọ́nì,+ ọmọ rẹ̀ ni Jòsáyà.+ 15 Àwọn ọmọ Jòsáyà ni Jóhánánì àkọ́bí, ìkejì ni Jèhóákímù,+ ìkẹta ni Sedekáyà,+ ìkẹrin ni Ṣálúmù. 16 Ọmọ* Jèhóákímù ni Jekonáyà,+ Sedekáyà sì ni ọmọ rẹ̀. 17 Àwọn ọmọ Jekonáyà ẹlẹ́wọ̀n ni Ṣéálítíẹ́lì, 18 Málíkírámù, Pedáyà, Ṣẹ́násà, Jekamáyà, Hóṣámà àti Nedabáyà. 19 Àwọn ọmọ Pedáyà ni Serubábélì+ àti Ṣíméì; àwọn ọmọ Serubábélì sì ni Méṣúlámù àti Hananáyà (Ṣẹ́lómítì ni arábìnrin wọn); 20 àwọn ọmọ márùn-ún míì ni Háṣúbà, Óhélì, Berekáyà, Hasadáyà àti Juṣabi-hésédì. 21 Àwọn ọmọ Hananáyà ni Pẹlatáyà àti Jeṣáyà; ọmọ* Jeṣáyà ni Refáyà; ọmọ* Refáyà ni Áánánì; ọmọ* Áánánì ni Ọbadáyà; ọmọ* Ọbadáyà ni Ṣẹkanáyà; 22 ọmọ* Ṣẹkanáyà ni Ṣemáyà, àwọn ọmọ Ṣemáyà sì ni: Hátúṣì, Ígálì, Baráyà, Nearáyà àti Ṣáfátì, gbogbo wọn jẹ́ mẹ́fà. 23 Àwọn ọmọ Nearáyà ni Élíóénáì, Hisikáyà àti Ásíríkámù, àwọn mẹ́ta. 24 Àwọn ọmọ Élíóénáì sì ni Hodafáyà, Élíáṣíbù, Pẹláyà, Ákúbù, Jóhánánì, Deláyà àti Ánáánì, àwọn méje.
4 Àwọn ọmọ Júdà ni Pérésì,+ Hésírónì,+ Kámì, Húrì+ àti Ṣóbálì.+ 2 Reáyà ọmọ Ṣóbálì bí Jáhátì; Jáhátì bí Áhúmáì àti Láhádì. Àwọn ni ìdílé àwọn Sórátì.+ 3 Àwọn ọmọ bàbá Étámì + nìyí: Jésírẹ́lì, Íṣímà àti Ídíbáṣì, (orúkọ arábìnrin wọn sì ni Haselelipónì), 4 Pénúélì ni bàbá* Gédórì, Ésérì sì ni bàbá Húṣà. Àwọn ni àwọn ọmọ Húrì,+ àkọ́bí Éfúrátà bàbá Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ 5 Áṣíhúrì+ bàbá Tékóà+ ní ìyàwó méjì, Hélà àti Náárà. 6 Náárà bí Áhúsámù, Héfà, Téménì àti Hááháṣítárì fún un. Àwọn ni àwọn ọmọ Náárà. 7 Àwọn ọmọ Hélà sì ni Sérétì, Ísárì àti Étínánì. 8 Kósì bí Ánúbù, Sóbébà àti àwọn ìdílé Áhárélì ọmọ Hárúmù.
9 Jábésì gbayì ju àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ; ìyá rẹ̀ sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jábésì,* ó sọ pé: “Mo bí i nínú ìrora.” 10 Jábésì ké pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ó ní: “Jọ̀wọ́ bù kún mi, kí o jẹ́ kí ìpínlẹ̀ mi fẹ̀ sí i, kí ọwọ́ rẹ wà pẹ̀lú mi, kí o sì pa mí mọ́ nínú àjálù, kí ó má bàa ṣe mí léṣe!” Torí náà, Ọlọ́run ṣe ohun tí ó béèrè.
11 Kélúbù arákùnrin Ṣúhà bí Méhírì tó jẹ́ bàbá Éṣítónì. 12 Éṣítónì bí Bẹti-ráfà, Páséà àti Téhínà bàbá Iri-náháṣì. Àwọn ló ń gbé ní Rékà. 13 Àwọn ọmọ Kénásì ni Ótíníẹ́lì+ àti Seráyà, ọmọ* Ótíníẹ́lì sì ni Hátátì. 14 Mèónótáì bí Ọ́fírà. Seráyà bí Jóábù bàbá Ge-háráṣímù,* wọ́n ń pè wọ́n bẹ́ẹ̀ torí pé oníṣẹ́ ọnà ni wọ́n.
15 Àwọn ọmọ Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè ni Írù, Élà àti Náámù; ọmọ* Élà sì ni Kénásì. 16 Àwọn ọmọ Jéhálélélì ni Sífù, Sífà, Tíríà àti Ásárélì. 17 Àwọn ọmọ Ésírà ni Jétà, Mérédì, Éférì àti Jálónì; ó* lóyún, ó sì bí Míríámù, Ṣámáì àti Íṣíbà bàbá Éṣítémóà. 18 (Mérédì ní ìyàwó Júù kan, òun ló bí Jérédì bàbá Gédórì, Hébà bàbá Sókò àti Jékútíélì bàbá Sánóà.) Àwọn ni ọmọ Bitáyà ọmọbìnrin Fáráò, tí Mérédì fẹ́.
19 Àwọn ọmọ ìyàwó Hodáyà, arábìnrin Náhámù ni olùtẹ̀dó* Kéílà ti àwọn ọmọ Gámì àti Éṣítémóà ti àwọn ará Máákátì. 20 Àwọn ọmọ Ṣímónì ni Ámínónì, Rínà, Bẹni-hánánì àti Tílónì. Àwọn ọmọ Íṣì sì ni Sóhétì àti Bẹni-sóhétì.
21 Àwọn ọmọ Ṣélà+ ọmọ Júdà ni Éérì bàbá Lékà, Láádà bàbá Máréṣà àti àwọn ìdílé àwọn tó ń hun aṣọ àtàtà ti ilé Áṣíbéà, 22 Jókímù, àwọn ọkùnrin Kósébà, Jóáṣì àti Sáráfì, àwọn ni wọ́n fi àwọn obìnrin ará Móábù ṣe aya àti Jaṣubi-léhémù. Àkọsílẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ ti àtijọ́.* 23 Àwọn ni amọ̀kòkò tó ń gbé Nétáímù àti Gédérà. Ibẹ̀ ni wọ́n ń gbé tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ fún ọba.
24 Àwọn ọmọ Síméónì+ ni Némúẹ́lì, Jámínì, Járíbù, Síírà àti Ṣéọ́lù.+ 25 Ọmọ rẹ̀ ni Ṣálúmù, ọmọ rẹ̀ ni Míbúsámù, ọmọ rẹ̀ sì ni Míṣímà. 26 Àwọn ọmọ Míṣímà ni Hámúélì, ọmọ* rẹ̀ ni Sákúrì, ọmọ rẹ̀ ni Ṣíméì. 27 Ṣíméì sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìndínlógún (16) àti ọmọbìnrin mẹ́fà; ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò ní ọmọ púpọ̀, kò sì sí ìkankan nínú ìdílé wọn tó ní ọmọ tó pọ̀ tó ti àwọn ọmọ Júdà.+ 28 Wọ́n ń gbé ní Bíá-ṣébà,+ Móládà,+ Hasari-ṣúálì,+ 29 Bílíhà, Ésémù,+ Tóládì, 30 Bẹ́túẹ́lì,+ Hóómà,+ Síkílágì,+ 31 Bẹti-mákábótì, Hasari-súsímù,+ Bẹti-bírì àti Ṣááráímù. Ìwọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà tí Dáfídì jọba.
32 Ibi tí wọ́n tẹ̀ dó sí ni Étámì, Áyínì, Rímónì, Tókénì àti Áṣánì,+ ìlú márùn-ún, 33 pẹ̀lú àwọn ibi tí wọ́n gbé tó wà yí ká gbogbo àwọn ìlú yìí títí dé Báálì. Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn tó wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn àti àwọn ibi tí wọ́n gbé. 34 Méṣóbábù, Jámílẹ́kì, Jóṣà ọmọ Amasááyà, 35 Jóẹ́lì, Jéhù ọmọ Joṣibáyà ọmọ Seráyà ọmọ Ásíélì, 36 Élíóénáì, Jáákóbà, Jeṣoháyà, Ásáyà, Ádíélì, Jésímíélì, Bẹnáyà 37 àti Sísà ọmọ Ṣífì ọmọ Álónì ọmọ Jedáyà ọmọ Ṣímúrì ọmọ Ṣemáyà; 38 àwọn tí a dárúkọ wọn yìí jẹ́ ìjòyè nínú ìdílé wọn, àwọn tó wà nínú agbo ilé àwọn baba ńlá wọn sì ń pọ̀ sí i. 39 Wọ́n lọ sí àbáwọlé Gédórì, sápá ìlà oòrùn àfonífojì, láti wá ibi ìjẹko fún àwọn agbo ẹran wọn. 40 Níkẹyìn, wọ́n rí àwọn ibi ìjẹko tó lọ́ràá tó sì dára, ilẹ̀ náà fẹ̀, ó pa rọ́rọ́, kò sì sí ìyọlẹ́nu níbẹ̀. Àwọn ọmọ Hámù+ ló ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀. 41 Àwọn tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ yìí jáde wá nígbà ayé Hẹsikáyà+ ọba Júdà, wọ́n sì wó àgọ́ àwọn ọmọ Hámù àti ti Méúnímù tó wà níbẹ̀ lulẹ̀. Wọ́n pa wọ́n run títí di òní yìí; wọ́n sì ń gbé ní àyè wọn, torí pé àwọn ibi tí agbo ẹran wọn ti lè máa jẹko wà níbẹ̀.
42 Àwọn kan lára àwọn ọmọ Síméónì, àwọn ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500), lọ sí Òkè Séírì+ pẹ̀lú Pẹlatáyà, Nearáyà, Refáyà àti Úsíélì, àwọn ọmọ Íṣì tí wọ́n ṣáájú wọn. 43 Wọ́n pa àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Ámálékì+ tó yè bọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.
5 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì,+ àkọ́bí Ísírẹ́lì nìyí. Òun ni àkọ́bí, àmọ́ torí pé ó kó ẹ̀gàn bá ibùsùn bàbá rẹ̀,*+ ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí ni a fún àwọn ọmọ Jósẹ́fù+ ọmọ Ísírẹ́lì, torí náà, wọn ò kọ orúkọ rẹ̀ sínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn pé òun ni àkọ́bí. 2 Òótọ́ ni pé Júdà+ ta yọ àwọn arákùnrin rẹ̀, ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ni ẹni tó máa jẹ́ aṣáájú+ ti wá, síbẹ̀ Jósẹ́fù ló ni ẹ̀tọ́ àkọ́bí. 3 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì ni Hánókù, Pálù, Hésírónì àti Kámì.+ 4 Àwọn ọmọ Jóẹ́lì ni Ṣemáyà, ọmọ* rẹ̀ ni Gọ́ọ̀gù, ọmọ rẹ̀ ni Ṣíméì, 5 ọmọ rẹ̀ ni Míkà, ọmọ rẹ̀ ni Reáyà, ọmọ rẹ̀ ni Báálì, 6 ọmọ rẹ̀ sì ni Bééráhì, ẹni tí Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà mú lọ sí ìgbèkùn; ó jẹ́ ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì. 7 Ìdílé àwọn arákùnrin rẹ̀ bí wọ́n ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn láti ìran dé ìran nìyí, àwọn tó jẹ́ olórí ni Jéélì, Sekaráyà 8 àti Bélà ọmọ Ásásì ọmọ Ṣímà ọmọ Jóẹ́lì, tí wọ́n ń gbé ní Áróérì+ títí dé Nébò àti Baali-méónì.+ 9 Wọ́n gbé ní apá ìlà oòrùn títí lọ dé àtiwọ aginjù tó wà ní odò Yúfírétì,+ torí ẹran ọ̀sìn wọn ti pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ Gílíádì.+ 10 Nígbà ayé Sọ́ọ̀lù, wọ́n bá àwọn ọmọ Hágárì jà, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn, torí náà, wọ́n ń gbé inú àwọn àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn Gílíádì.
11 Lákòókò yìí, àwọn ọmọ Gádì ń gbé nítòsí wọn láti ilẹ̀ Báṣánì títí dé Sálékà.+ 12 Ní Báṣánì, Jóẹ́lì ni olórí, Ṣáfámù ni igbá kejì, Jánáì àti Ṣáfátì náà wà níbẹ̀. 13 Àwọn arákùnrin wọn tó wá láti agbo ilé bàbá wọn ni Máíkẹ́lì, Méṣúlámù, Ṣébà, Jóráì, Jákánì, Sáyà àti Ébérì, gbogbo wọn jẹ́ méje. 14 Àwọn ni àwọn ọmọ Ábíháílì ọmọ Húúrì, ọmọ Járóà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Máíkẹ́lì, ọmọ Jéṣíṣáì, ọmọ Jádò, ọmọ Búsì. 15 Áhì ọmọ Ábídíélì, ọmọ Gúnì ni olórí ẹbí wọn. 16 Wọ́n gbé ní Gílíádì,+ ní Báṣánì+ àti ní àwọn àrọko* rẹ̀ àti ní gbogbo àwọn ibi ìjẹko Ṣárónì títí dé ibi tí wọ́n fẹ̀ dé. 17 Gbogbo wọn ni orúkọ wọn wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn nígbà ayé Jótámù+ ọba Júdà àti nígbà ayé Jèróbóámù*+ ọba Ísírẹ́lì.
18 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti ọgọ́ta (44,760) jagunjagun tó lákíkanjú, wọ́n ń gbé apata, wọ́n ń lo idà, wọ́n mọ ọfà lò,* wọ́n sì ti kọ́ iṣẹ́ ogun. 19 Wọ́n bá àwọn ọmọ Hágárì,+ Jétúrì, Náfíṣì+ àti Nódábù jagun. 20 Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bá wọn jà, tó fi jẹ́ pé a fi àwọn ọmọ Hágárì àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú wọn lé wọn lọ́wọ́, torí pé wọ́n ké pe Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ nínú ogun náà, ó sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.+ 21 Wọ́n kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ (50,000) ràkúnmí, ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ (250,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) èèyàn.* 22 Ọ̀pọ̀ ló kú, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ ló ja ìjà náà.+ Wọ́n gba àyè wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí dìgbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn.+
23 Àtọmọdọ́mọ ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ gbé ilẹ̀ náà láti Báṣánì dé Baali-hámónì àti Sénírì àti Òkè Hámónì.+ Wọ́n pọ̀ gan-an. 24 Àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn nìyí: Éférì, Íṣì, Élíélì, Ásíríẹ́lì, Jeremáyà, Hodafáyà àti Jádíẹ́lì; jagunjagun tó lákíkanjú ni wọ́n, wọ́n lókìkí, àwọn sì ni olórí agbo ilé bàbá wọn. 25 Àmọ́ wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, wọ́n sì ń bá àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn ilẹ̀ náà+ ṣe àgbèrè, àwọn tí Ọlọ́run pa run kúrò níwájú wọn. 26 Nítorí náà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi èrò kan sọ́kàn* Púlì ọba Ásíríà+ (ìyẹn, Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà), tí ó fi kó àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè lọ sí ìgbèkùn, ó kó wọn wá sí Hálà, Hábórì, Hárà àti odò Gósánì,+ ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní yìí.
6 Àwọn ọmọ Léfì+ ni Gẹ́ṣónì, Kóhátì+ àti Mérárì.+ 2 Àwọn ọmọ Kóhátì ni Ámúrámù, Ísárì,+ Hébúrónì àti Úsíélì.+ 3 Àwọn ọmọ* Ámúrámù+ ni Áárónì,+ Mósè+ àti Míríámù.+ Àwọn ọmọ Áárónì sì ni Nádábù, Ábíhù,+ Élíásárì+ àti Ítámárì.+ 4 Élíásárì bí Fíníhásì;+ Fíníhásì bí Ábíṣúà. 5 Ábíṣúà bí Búkì; Búkì bí Úsáì. 6 Úsáì bí Seraháyà; Seraháyà bí Méráótì. 7 Méráótì bí Amaráyà; Amaráyà bí Áhítúbù.+ 8 Áhítúbù bí Sádókù;+ Sádókù bí Áhímáásì.+ 9 Áhímáásì bí Asaráyà; Asaráyà bí Jóhánánì. 10 Jóhánánì bí Asaráyà. Ó ṣe iṣẹ́ àlùfáà ní ilé tí Sólómọ́nì kọ́ sí Jerúsálẹ́mù.
11 Asaráyà bí Amaráyà; Amaráyà bí Áhítúbù. 12 Áhítúbù bí Sádókù;+ Sádókù bí Ṣálúmù. 13 Ṣálúmù bí Hilikáyà;+ Hilikáyà bí Asaráyà. 14 Asaráyà bí Seráyà;+ Seráyà bí Jèhósádákì.+ 15 Jèhósádákì lọ sí ìgbèkùn nígbà tí Jèhófà mú kí Nebukadinésárì kó Júdà àti Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn.
16 Àwọn ọmọ Léfì ni Gẹ́ṣómù,* Kóhátì àti Mérárì. 17 Orúkọ àwọn ọmọ Gẹ́ṣómù nìyí: Líbínì àti Ṣíméì.+ 18 Àwọn ọmọ Kóhátì ni Ámúrámù, Ísárì, Hébúrónì àti Úsíélì.+ 19 Àwọn ọmọ Mérárì ni Máhílì àti Múṣì.
Ìdílé àwọn baba ńlá àwọn ọmọ Léfì+ nìwọ̀nyí: 20 Ní ti Gẹ́ṣómù,+ ọmọ* rẹ̀ ni Líbínì, ọmọ rẹ̀ ni Jáhátì, ọmọ rẹ̀ ni Símà, 21 ọmọ rẹ̀ ni Jóà, ọmọ rẹ̀ ni Ídò, ọmọ rẹ̀ ni Síírà, ọmọ rẹ̀ sì ni Jéátéráì. 22 Àwọn ọmọ* Kóhátì ni Ámínádábù, ọmọ rẹ̀ ni Kórà,+ ọmọ rẹ̀ ni Ásírì, 23 ọmọ rẹ̀ ni Ẹlikénà, ọmọ rẹ̀ ni Ébíásáfù,+ ọmọ rẹ̀ ni Ásírì, 24 ọmọ rẹ̀ ni Táhátì, ọmọ rẹ̀ ni Úríélì, ọmọ rẹ̀ ni Ùsáyà, ọmọ rẹ̀ sì ni Ṣéọ́lù. 25 Àwọn ọmọ Ẹlikénà ni Ámásáì àti Áhímótì. 26 Ní ti Ẹlikénà, àwọn ọmọ Ẹlikénà ni Sófáì, ọmọ rẹ̀ ni Náhátì, 27 ọmọ rẹ̀ ni Élíábù, ọmọ rẹ̀ ni Jéróhámù, ọmọ rẹ̀ ni Ẹlikénà.+ 28 Àwọn ọmọ Sámúẹ́lì+ ni Jóẹ́lì àkọ́bí àti ìkejì Ábíjà.+ 29 Àwọn ọmọ* Mérárì ni Máhílì,+ ọmọ rẹ̀ ni Líbínì, ọmọ rẹ̀ ni Ṣíméì, ọmọ rẹ̀ ni Úsà, 30 ọmọ rẹ̀ ni Ṣíméà, ọmọ rẹ̀ ni Hagáyà, ọmọ rẹ̀ sì ni Ásáyà.
31 Àwọn tí Dáfídì yàn pé kí wọ́n máa darí orin ní ilé Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n gbé Àpótí náà síbẹ̀ nìyí.+ 32 Ojúṣe wọn ni láti máa kọrin ní àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn ni àgọ́ ìpàdé títí di ìgbà tí Sólómọ́nì kọ́ ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún wọn bí wọ́n ṣe ni kí wọ́n máa ṣe é.+ 33 Àwọn tó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn nìyí: Látinú àwọn ọmọ Kóhátì, Hémánì+ akọrin, ọmọ Jóẹ́lì,+ ọmọ Sámúẹ́lì, 34 ọmọ Ẹlikénà,+ ọmọ Jéróhámù, ọmọ Élíélì, ọmọ Tóà, 35 ọmọ Súfì, ọmọ Ẹlikénà, ọmọ Máhátì, ọmọ Ámásáì, 36 ọmọ Ẹlikénà, ọmọ Jóẹ́lì, ọmọ Asaráyà, ọmọ Sefanáyà, 37 ọmọ Táhátì, ọmọ Ásírì, ọmọ Ébíásáfù, ọmọ Kórà, 38 ọmọ Ísárì, ọmọ Kóhátì, ọmọ Léfì, ọmọ Ísírẹ́lì.
39 Ásáfù+ arákùnrin rẹ̀* dúró ní apá ọ̀tún Hémánì; Ásáfù jẹ́ ọmọ Berekáyà, ọmọ Ṣíméà, 40 ọmọ Máíkẹ́lì, ọmọ Baaseáyà, ọmọ Málíkíjà, 41 ọmọ Étínì, ọmọ Síírà, ọmọ Ádáyà, 42 ọmọ Étánì, ọmọ Símà, ọmọ Ṣíméì, 43 ọmọ Jáhátì, ọmọ Gẹ́ṣómù, ọmọ Léfì.
44 Àwọn ọmọ Mérárì+ arákùnrin wọn wà ní apá òsì; ibẹ̀ ni Étánì+ wà, ọmọ Kííṣì, ọmọ Ábídì, ọmọ Málúkù, 45 ọmọ Haṣabáyà, ọmọ Amasááyà, ọmọ Hilikáyà, 46 ọmọ Ámísì, ọmọ Bánì, ọmọ Ṣémérì, 47 ọmọ Máhílì, ọmọ Múṣì, ọmọ Mérárì, ọmọ Léfì.
48 Àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọmọ Léfì ni a yàn* láti máa ṣe gbogbo iṣẹ́ àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn ilé Ọlọ́run tòótọ́.+ 49 Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀+ mú ẹbọ rú èéfín lórí pẹpẹ ẹbọ sísun+ àti lórí pẹpẹ tùràrí,+ wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ àwọn ohun mímọ́ jù lọ, láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì,+ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ. 50 Àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì+ nìyí: ọmọ* rẹ̀ ni Élíásárì,+ ọmọ rẹ̀ ni Fíníhásì, ọmọ rẹ̀ ni Ábíṣúà, 51 ọmọ rẹ̀ ni Búkì, ọmọ rẹ̀ ni Úsáì, ọmọ rẹ̀ ni Seraháyà, 52 ọmọ rẹ̀ ni Méráótì, ọmọ rẹ̀ ni Amaráyà, ọmọ rẹ̀ ni Áhítúbù,+ 53 ọmọ rẹ̀ ni Sádókù,+ ọmọ rẹ̀ ni Áhímáásì.
54 Bí a ṣe ṣètò wọn sí ibùdó wọn* ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ń gbé nìyí: fún àwọn ọmọ Áárónì tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì, nítorí ọwọ́ wọn ni ìpín àkọ́kọ́ bọ́ sí, 55 wọ́n fún wọn ní Hébúrónì+ ní ilẹ̀ Júdà pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko tó yí i ká. 56 Àmọ́ Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè ni wọ́n fún ní pápá tó wà ní ìlú náà àti àwọn ìletò rẹ̀. 57 Àwọn ọmọ Áárónì ni wọ́n fún ní àwọn ìlú* ààbò,+ Hébúrónì+ àti Líbínà+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Játírì+ àti Éṣítémóà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko rẹ̀,+ 58 Hílénì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Débírì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 59 Áṣánì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Bẹti-ṣémẹ́ṣì + pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀; 60 láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Gébà+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Álémétì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Ánátótì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n fún ìdílé wọn jẹ́ mẹ́tàlá (13).+
61 Wọ́n fún* àwọn ọmọ Kóhátì tó ṣẹ́ kù ní ìlú mẹ́wàá, látinú ìdílé ẹ̀yà náà, látinú ààbọ̀ ẹ̀yà náà, ààbọ̀ Mánásè.+
62 Wọ́n fún àwọn ọmọ Gẹ́ṣómù àti àwọn ìdílé wọn ní ìlú mẹ́tàlá (13) látinú ẹ̀yà Ísákà, ẹ̀yà Áṣérì, ẹ̀yà Náfútálì àti ẹ̀yà Mánásè ní Báṣánì.+
63 Wọ́n ṣẹ́ kèké, wọ́n sì fún àwọn ọmọ Mérárì àti àwọn ìdílé wọn ní ìlú méjìlá (12) látinú ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ẹ̀yà Sébúlúnì.+
64 Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú yìí pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko+ wọn nìyẹn. 65 Síwájú sí i, wọ́n ṣẹ́ kèké, wọ́n sì pín àwọn ìlú tí a dárúkọ yìí, èyí tí wọ́n gbà látinú ẹ̀yà Júdà, ẹ̀yà Síméónì àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.
66 Àwọn kan lára ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì gba àwọn ìlú látinú ẹ̀yà Éfúrémù láti fi ṣe ìpínlẹ̀ wọn.+ 67 Wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú* ààbò, Ṣékémù+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ ní agbègbè olókè Éfúrémù, Gésérì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 68 Jókíméámù pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Bẹti-hórónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 69 Áíjálónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Gati-rímónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀; 70 látinú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, a fún ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì tí ó ṣẹ́ kù ní Ánérì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Bíléámù pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀.
71 Látinú ìdílé ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, wọ́n fún àwọn ọmọ Gẹ́ṣómù ní Gólánì+ tó wà ní Báṣánì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Áṣítárótì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀;+ 72 látinú ẹ̀yà Ísákà, Kédéṣì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Dábérátì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀,+ 73 Rámótì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Ánémù pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀; 74 látinú ẹ̀yà Áṣérì, Máṣálì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Ábídónì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀,+ 75 Húkọ́kù pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Réhóbù+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀; 76 látinú ẹ̀yà Náfútálì, Kédéṣì+ ní Gálílì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Hámónì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Kíríátáímù pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀.
77 Látinú ẹ̀yà Sébúlúnì,+ wọ́n fún àwọn ọmọ Mérárì tó ṣẹ́ kù ní Rímónò pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Tábórì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀; 78 láti ara ilẹ̀ ẹ̀yà Rúbẹ́nì tó wà ní agbègbè ilẹ̀ Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò títí dé apá ìlà oòrùn Jọ́dánì, wọ́n fún wọn ní Bésérì tó wà ní aginjù pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Jáhásì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 79 Kédémótì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Mẹ́fáátì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀; 80 látinú ẹ̀yà Gádì, Rámótì ní Gílíádì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Máhánáímù+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 81 Hẹ́ṣíbónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Jásérì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀.
7 Àwọn ọmọ Ísákà ni Tólà, Púà, Jáṣúbù àti Ṣímúrónì,+ wọ́n jẹ́ mẹ́rin. 2 Àwọn ọmọ Tólà ni Úsáì, Refáyà, Jéríélì, Jámáì, Íbísámù àti Ṣẹ́múẹ́lì, àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn. Àwọn àtọmọdọ́mọ Tólà jẹ́ jagunjagun tó lákíkanjú, iye wọn ní ìgbà ayé Dáfídì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (22,600). 3 Àwọn àtọmọdọ́mọ* Úsáì ni Isiráháyà, àwọn ọmọ Isiráháyà sì ni: Máíkẹ́lì, Ọbadáyà, Jóẹ́lì àti Isiṣáyà, àwọn márààrún jẹ́ ìjòyè.* 4 Àwọn àti àtọmọdọ́mọ wọn tó wà ní àwọn agbo ilé bàbá wọn, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) ọmọ ogun ni ó wà ní sẹpẹ́ fún ogun, nítorí wọ́n ní ìyàwó àti ọmọ púpọ̀. 5 Àwọn arákùnrin wọn tó wà ní gbogbo ìdílé Ísákà jẹ́ jagunjagun tó lákíkanjú. Gbogbo wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún (87,000), bí orúkọ wọn ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.+
6 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì+ ni Bélà,+ Békérì+ àti Jédáélì,+ wọ́n jẹ́ mẹ́ta. 7 Àwọn ọmọ Bélà ni Ésíbónì, Úsáì, Úsíélì, Jérímótì àti Íráì, àwọn márùn-ún, àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn, àwọn jagunjagun tó lákíkanjú, orúkọ àwọn ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (22,034) ni ó sì wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.+ 8 Àwọn ọmọ Békérì ni Sémírà, Jóáṣì, Élíésérì, Élíóénáì, Ómírì, Jérémótì, Ábíjà, Ánátótì àti Álémétì, gbogbo àwọn yìí ni ọmọ Békérì. 9 Àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó wà ní agbo ilé bàbá wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé igba (20,200) jagunjagun tó lákíkanjú, orúkọ wọn sì wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn. 10 Àwọn ọmọ Jédáélì+ ni Bílíhánì, àwọn ọmọ Bílíhánì sì ni: Jéúṣì, Bẹ́ńjámínì, Éhúdù, Kénáánà, Sẹ́tánì, Táṣíṣì àti Áhíṣáhárì. 11 Gbogbo wọn ni ọmọ Jédáélì, wọ́n jẹ́ olórí agbo ilé àwọn baba ńlá wọn, àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún ó lé igba (17,200) jagunjagun tó lákíkanjú tí wọ́n ti gbára dì láti jáde ogun.
12 Àwọn Ṣúpímù àti àwọn Húpímù ni àwọn ọmọ Írì;+ àwọn Húṣímù ni àwọn ọmọ Áhérì.
13 Àwọn ọmọ Náfútálì+ ni Jásíélì, Gúnì, Jésérì àti Ṣálúmù, àwọn àtọmọdọ́mọ* Bílíhà.+
14 Àwọn ọmọ Mánásè+ ni: Ásíríélì, tí wáhàrì* rẹ̀ ará Síríà bí. (Ó bí Mákírù+ bàbá Gílíádì. 15 Mákírù fẹ́ ìyàwó fún Húpímù àti fún Ṣúpímù, orúkọ arábìnrin rẹ̀ sì ni Máákà.) Orúkọ ìkejì ni Sélóféhádì,+ àmọ́ àwọn ọmọbìnrin ni Sélóféhádì bí.+ 16 Máákà, ìyàwó Mákírù bí ọmọ kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Péréṣì; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Ṣéréṣì; àwọn ọmọ rẹ̀ sì ni Úlámù àti Rékémù. 17 Ọmọ* Úlámù ni Bédánì. Àwọn ni ọmọ Gílíádì ọmọ Mákírù ọmọ Mánásè. 18 Arábìnrin rẹ̀ ni Hámólékétì. Ó bí Íṣíhódù, Abi-ésérì àti Málà. 19 Àwọn ọmọ Ṣẹ́mídà ni Áhíánì, Ṣékémù, Líkíhì àti Áníámù.
20 Àwọn ọmọ Éfúrémù+ ni Ṣútélà,+ ọmọ* rẹ̀ ni Bérédì, ọmọ rẹ̀ ni Táhátì, ọmọ rẹ̀ ni Éléádà, ọmọ rẹ̀ ni Táhátì, 21 ọmọ rẹ̀ ni Sábádì, ọmọ rẹ̀ ni Ṣútélà àti Ésérì pẹ̀lú Éléádì. Àwọn ọkùnrin Gátì+ tí wọ́n bí ní ilẹ̀ náà pa wọ́n torí pé wọ́n lọ kó ẹran ọ̀sìn wọn. 22 Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni Éfúrémù bàbá wọn fi ṣọ̀fọ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti tù ú nínú. 23 Lẹ́yìn náà, ó ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, ó lóyún, ó sì bímọ. Àmọ́ ó pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹráyà,* torí pé inú àjálù ni agbo ilé rẹ̀ wà nígbà tí ìyàwó rẹ̀ bímọ. 24 Ọmọbìnrin rẹ̀ ni Ṣéérà, òun ló tẹ ìlú Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀+ àti ti Òkè+ dó àti Useni-ṣéérà. 25 Ọmọ rẹ̀ ni Réfà àti Réṣéfù, ọmọ rẹ̀ ni Télà ọmọ rẹ̀ sì ni Táhánì, 26 ọmọ rẹ̀ ni Ládánì, ọmọ rẹ̀ ni Ámíhúdù, ọmọ rẹ̀ ni Élíṣámà, 27 ọmọ rẹ̀ ni Núnì, ọmọ rẹ̀ sì ni Jóṣúà.*+
28 Àwọn ibi tí wọ́n ń gbé àti ohun ìní wọn ni Bẹ́tẹ́lì+ àti àwọn àrọko* rẹ̀, Nááránì ní apá ìlà oòrùn, Gésérì ní apá ìwọ̀ oòrùn àti àwọn àrọko rẹ̀ pẹ̀lú Ṣékémù àti àwọn àrọko rẹ̀ títí dé Ááyà* àti àwọn àrọko rẹ̀; 29 àwọn ilẹ̀ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti àwọn àtọmọdọ́mọ Mánásè ni, Bẹti-ṣéánì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, Táánákì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, Mẹ́gídò+ àti àwọn àrọko rẹ̀, Dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀. Orí àwọn ilẹ̀ yìí ni àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù ọmọ Ísírẹ́lì gbé.
30 Àwọn ọmọkùnrin Áṣérì ni Ímúnà, Íṣífà, Íṣífì àti Bẹráyà,+ pẹ̀lú Sírà+ arábìnrin wọn. 31 Àwọn ọmọ Bẹráyà ni Hébà àti Málíkíélì, òun ni bàbá Bísáítì. 32 Hébà bí Jáfílétì, Ṣómà, Hótámù àti Ṣúà arábìnrin wọn. 33 Àwọn ọmọ Jáfílétì ni Pásákì, Bímíhálì àti Áṣífátì. Àwọn ni ọmọ Jáfílétì. 34 Àwọn ọmọ Ṣémérì* ni Áhì, Rógà, Jéhúbà àti Árámù. 35 Àwọn ọmọ Hélémù* arákùnrin rẹ̀ ni Sófà, Ímínà, Ṣéléṣì àti Ámálì. 36 Àwọn ọmọ Sófà ni Súà, Hánéfà, Ṣúálì, Bérì, Ímúrà, 37 Bésérì, Hódì, Ṣáámà, Ṣílíṣà, Ítíránì àti Béérà. 38 Àwọn ọmọ Jétà ni Jéfúnè, Písípà àti Árà. 39 Àwọn ọmọ Úlà ni Áráhì, Háníélì àti Rísíà. 40 Gbogbo wọn ni ọmọ Áṣérì, àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn, àwọn tí a yàn, àwọn jagunjagun tó lákíkanjú, àwọn olórí ìjòyè; iye wọn bí ó ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé+ wọn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26,000) ọkùnrin+ ogun tí wọ́n ti gbára dì fún ogun.
8 Bẹ́ńjámínì+ bí Bélà+ àkọ́bí rẹ̀, ọmọ rẹ̀ kejì ni Áṣíbélì,+ ìkẹta ni Áhárà, 2 ìkẹrin ni Nóhà, ìkarùn-ún sì ni Ráfà. 3 Àwọn ọmọ Bélà ni Ádáárì, Gérà,+ Ábíhúdù, 4 Ábíṣúà, Náámánì, Áhóà, 5 Gérà, Ṣéfúfánì àti Húrámù. 6 Àwọn ọmọ Éhúdù nìyí, wọ́n jẹ́ olórí agbo ilé àwọn tó ń gbé Gébà,+ àwọn tí wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn ní Mánáhátì, àwọn ni: 7 Náámánì, Áhíjà àti Gérà. Gérà yìí ló kó wọn lọ sí ìgbèkùn, ó sì bí Úúsà àti Áhíhúdù. 8 Ṣáháráímù bí àwọn ọmọ ní ilẹ̀* Móábù lẹ́yìn tí ó lé wọn kúrò. Àwọn ìyàwó rẹ̀ sì ni Húṣímù àti Báárà.* 9 Ìyàwó rẹ̀ Hódéṣì bí àwọn ọmọ fún un, àwọn ni: Jóbábù, Síbíà, Méṣà, Málíkámù, 10 Jéúsì, Sákíà àti Mírímà. Àwọn ni ọmọ rẹ̀, olórí sì ni wọ́n nínú agbo ilé bàbá wọn.
11 Húṣímù bí Ábítúbù àti Élípáálì fún un. 12 Àwọn ọmọ Élípáálì ni Ébérì, Míṣámù àti Ṣémédì (òun ló kọ́ Ónò+ àti Lódì+ pẹ̀lú àwọn àrọko* rẹ̀), 13 Bẹráyà àti Ṣímà. Àwọn ni olórí agbo ilé àwọn tó ń gbé Áíjálónì.+ Àwọn ló lé àwọn tó ń gbé ní Gátì lọ. 14 Áhíò, Ṣáṣákì, Jérémótì, 15 Sebadáyà, Árádì, Édérì, 16 Máíkẹ́lì, Íṣípà, Jóhà, àwọn ọmọ Bẹráyà; 17 àti Sebadáyà, Méṣúlámù, Hísíkì, Hébà, 18 Íṣíméráì, Isiláyà, Jóbábù, àwọn ọmọ Élípáálì; 19 Jákímù, Síkírì, Sábídì, 20 Élíénáì, Sílétáì, Élíélì, 21 Ádáyà, Bẹráyà, Ṣímúrátì, àwọn ọmọ Ṣíméì; 22 Íṣípánì, Ébérì, Élíélì, 23 Ábídónì, Síkírì, Hánánì, 24 Hananáyà, Élámù, Áńtótíjà, 25 Ifidéáyà, Pénúélì, àwọn ọmọ Ṣáṣákì; 26 Ṣámúṣéráì, Ṣẹharáyà, Ataláyà, 27 Jaareṣáyà, Èlíjà, Síkírì, àwọn ọmọ Jéróhámù. 28 Àwọn ni olórí agbo ilé àwọn àtọmọdọ́mọ wọn. Jerúsálẹ́mù ni àwọn olórí yìí ń gbé.
29 Jéélì gbé ní Gíbíónì,+ òun ló sì tẹ ìlú náà dó. Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Máákà.+ 30 Àkọ́bí rẹ̀ ọkùnrin ni Ábídónì, àwọn tó tẹ̀ lé e ni Súúrì, Kíṣì, Báálì, Nádábù, 31 Gédórì, Áhíò àti Sékà. 32 Míkílótì bí Ṣímẹ́à. Gbogbo wọn gbé nítòsí àwọn arákùnrin wọn ní Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn míì.
33 Nérì+ bí Kíṣì; Kíṣì bí Sọ́ọ̀lù;+ Sọ́ọ̀lù bí Jónátánì,+ Maliki-ṣúà,+ Ábínádábù+ àti Eṣibáálì.*+ 34 Ọmọ Jónátánì ni Meribu-báálì.*+ Meribu-báálì bí Míkà.+ 35 Àwọn ọmọ Míkà ni Pítónì, Mélékì, Táréà àti Áhásì. 36 Áhásì bí Jẹ̀hóádà; Jẹ̀hóádà bí Álémétì, Ásímáfẹ́tì àti Símírì. Símírì bí Mósà. 37 Mósà bí Bínéà, ọmọ* rẹ̀ ni Ráfáhì, ọmọ rẹ̀ ni Éléásà, ọmọ rẹ̀ sì ni Ásélì. 38 Ásélì ní ọmọkùnrin mẹ́fà, orúkọ wọn ni Ásíríkámù, Bókérù, Íṣímáẹ́lì, Ṣearáyà, Ọbadáyà àti Hánánì. Gbogbo wọn ni ọmọ Ásélì. 39 Àwọn ọmọ Éṣékì arákùnrin rẹ̀ ni Úlámù àkọ́bí rẹ̀, ọmọ rẹ̀ kejì ni Jéúṣì, ìkẹta sì ni Élífélétì. 40 Àwọn ọmọ Úlámù jẹ́ jagunjagun tó lákíkanjú tó mọ ọfà lò,* wọn ni ọ̀pọ̀ ọmọ àti ọmọ ọmọ, iye wọn jẹ́ àádọ́jọ (150). Gbogbo àwọn yìí jẹ́ àtọmọdọ́mọ Bẹ́ńjámínì.
9 Orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn, a sì kọ wọ́n sínú Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ Júdà ni a sì kó lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì nítorí ìwà àìṣòótọ́+ wọn. 2 Àwọn tó kọ́kọ́ pa dà sídìí ohun ìní wọn, ní àwọn ìlú wọn, ni àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì.*+ 3 Lára àwọn ọmọ Júdà+ àti lára àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì+ àti lára àwọn ọmọ Éfúrémù pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn ọmọ Mánásè ń gbé Jerúsálẹ́mù, àwọn ni: 4 Útáì ọmọ Ámíhúdù ọmọ Ómírì ọmọ Ímúrì ọmọ Bánì, tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Pérésì+ ọmọ Júdà. 5 Látinú àwọn ọmọ Ṣílò, Ásáyà àkọ́bí àti àwọn ọmọ rẹ̀. 6 Látinú àwọn ọmọ Síírà,+ Júẹ́lì àti ọgọ́rùn-ún méje ó dín mẹ́wàá (690) lára àwọn arákùnrin wọn.
7 Látinú àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, Sáálù ọmọ Méṣúlámù ọmọ Hodafáyà ọmọ Hásénúà, 8 Ibineáyà ọmọ Jéróhámù, Élà ọmọ Úsáì ọmọ Míkírì àti Méṣúlámù ọmọ Ṣẹfatáyà ọmọ Réúẹ́lì ọmọ Ibiníjà. 9 Àwọn arákùnrin wọn láti ìran wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé àádọ́ta àti mẹ́fà (956). Gbogbo wọn jẹ́ olórí ní agbo ilé bàbá wọn.*
10 Látinú àwọn àlùfáà, Jedáyà, Jèhóáríbù, Jákínì,+ 11 Asaráyà ọmọ Hilikáyà ọmọ Méṣúlámù ọmọ Sádókù ọmọ Méráótì ọmọ Áhítúbù, aṣáájú ní ilé* Ọlọ́run tòótọ́, 12 Ádáyà ọmọ Jéróhámù ọmọ Páṣúrì ọmọ Málíkíjà, Máásáì ọmọ Ádíélì ọmọ Jásérà ọmọ Méṣúlámù ọmọ Méṣílẹ́mítì ọmọ Ímérì 13 àti àwọn arákùnrin wọn, àwọn ni olórí agbo ilé bàbá wọn, ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti ọgọ́ta (1,760) ọkùnrin tó dáńgájíá tí wọ́n wà fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́.
14 Látinú àwọn ọmọ Léfì, Ṣemáyà+ ọmọ Háṣúbù ọmọ Ásíríkámù ọmọ Haṣabáyà látinú àwọn àtọmọdọ́mọ Mérárì 15 àti Bakibákárì, Héréṣì, Gálálì, Matanáyà ọmọ Máíkà ọmọ Síkírì ọmọ Ásáfù, 16 Ọbadáyà ọmọ Ṣemáyà ọmọ Gálálì ọmọ Jédútúnì àti Berekáyà ọmọ Ásà ọmọ Ẹlikénà, ẹni tó ń gbé ní ibi tí àwọn ará Nétófà+ tẹ̀ dó sí.
17 Àwọn aṣọ́bodè+ ni Ṣálúmù, Ákúbù, Tálímónì, Áhímánì àti Ṣálúmù arákùnrin wọn tó jẹ́ olórí, 18 títí di ìgbà náà, ẹnubodè ọba lápá ìlà oòrùn+ ni ó wà. Àwọn ni aṣọ́bodè ibùdó àwọn ọmọ Léfì. 19 Ṣálúmù ọmọ Kórè ọmọ Ébíásáfù ọmọ Kórà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ láti agbo ilé bàbá rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Kórà, ló ń bójú tó iṣẹ́ náà, àwọn aṣọ́nà àgọ́, àwọn bàbá wọn ló sì ń bójú tó ibùdó Jèhófà torí àwọn ló ń ṣọ́ ọ̀nà àbáwọlé. 20 Fíníhásì+ ọmọ Élíásárì+ ni aṣáájú wọn tẹ́lẹ̀; Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 21 Sekaráyà+ ọmọ Meṣelemáyà ni aṣọ́bodè ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
22 Gbogbo àwọn tí wọ́n yàn ṣe aṣọ́bodè ní àwọn ibi àbáwọlé jẹ́ igba ó lé méjìlá (212). Wọ́n wà ní ibi tí wọ́n tẹ̀ dó sí bí orúkọ wọn ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.+ Dáfídì àti Sámúẹ́lì aríran+ ló yàn wọ́n sí ipò ẹni tó ṣeé fọkàn tán tí wọ́n wà. 23 Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ló ń ṣọ́ àwọn ẹnubodè ilé Jèhófà,+ ìyẹn ilé àgọ́. 24 Àwọn aṣọ́bodè wà ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìyẹn ní ìlà oòrùn, ìwọ̀ oòrùn, àríwá àti gúúsù.+ 25 Látìgbàdégbà, àwọn arákùnrin wọn máa ń wá láti àwọn ibi tí wọ́n tẹ̀ dó sí láti bá wọn ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ méje. 26 Àwọn olórí* aṣọ́bodè mẹ́rin ló wà ní ipò ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Ọmọ Léfì ni wọ́n, àwọn ló sì ń bójú tó àwọn yàrá* àti àwọn ibi ìṣúra tó wà nínú ilé Ọlọ́run tòótọ́.+ 27 Wọ́n máa ń wà níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ káàkiri ilé Ọlọ́run tòótọ́ láti òru mọ́jú, nítorí àwọn ló ń ṣe iṣẹ́ olùṣọ́, ọwọ́ wọn ni kọ́kọ́rọ́ máa ń wà, àwọn ló sì ń ṣí ilé náà láràárọ̀.
28 Àwọn kan lára wọn ń bójú tó àwọn ohun èlò+ tó wà fún ìjọsìn; wọ́n máa ń kà wọ́n tí wọ́n bá ń kó wọn wọlé àti nígbà tí wọ́n bá ń kó wọn jáde. 29 Wọ́n yan àwọn kan lára wọn láti máa bójú tó àwọn ohun èlò, gbogbo àwọn ohun èlò mímọ́,+ ìyẹ̀fun kíkúnná,+ wáìnì,+ òróró,+ oje igi tùràrí+ àti òróró básámù.+ 30 Àwọn kan lára àwọn ọmọ àlùfáà máa ń po ìpara tí ó ní òróró básámù. 31 Matitáyà tó wá látinú àwọn ọmọ Léfì, òun ni àkọ́bí Ṣálúmù ọmọ Kórà, òun ló wà ní ipò ẹni tó ṣeé fọkàn tán tó ń bójú tó yíyan àwọn nǹkan nínú páànù.+ 32 Àwọn kan lára àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Kóhátì ló ń bójú tó búrẹ́dì onípele,*+ láti ṣe é sílẹ̀ ní sábáàtì+ kọ̀ọ̀kan.
33 Àwọn yìí ni àwọn akọrin, àwọn olórí agbo ilé àwọn ọmọ Léfì nínú àwọn yàrá,* àwọn tí a kò yan iṣẹ́ míì fún; nítorí pé ojúṣe wọn ni láti máa wà lẹ́nu iṣẹ́ tọ̀sántòru. 34 Àwọn ni olórí agbo ilé àwọn ọmọ Léfì ní ìran wọn, wọ́n jẹ́ aṣáájú. Jerúsálẹ́mù ni wọ́n sì ń gbé.
35 Jéélì gbé ní Gíbíónì,+ òun ló sì tẹ ìlú náà dó. Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Máákà. 36 Àkọ́bí rẹ̀ ọkùnrin ni Ábídónì, àwọn tó tẹ̀ lé e ni Súúrì, Kíṣì, Báálì, Nérì, Nádábù, 37 Gédórì, Áhíò, Sekaráyà àti Míkílótì. 38 Míkílótì bí Ṣíméámù. Gbogbo wọn gbé nítòsí àwọn arákùnrin wọn ní Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn míì. 39 Nérì+ bí Kíṣì; Kíṣì bí Sọ́ọ̀lù;+ Sọ́ọ̀lù bí Jónátánì,+ Maliki-ṣúà,+ Ábínádábù+ àti Eṣibáálì. 40 Ọmọ Jónátánì ni Meribu-báálì.+ Meribu-báálì bí Míkà.+ 41 Àwọn ọmọ Míkà ni Pítónì, Mélékì, Tááréà àti Áhásì. 42 Áhásì bí Járà; Járà bí Álémétì, Ásímáfẹ́tì àti Símírì. Símírì bí Mósà. 43 Mósà bí Bínéà àti Refáyà, ọmọ* rẹ̀ ni Éléásà, ọmọ rẹ̀ sì ni Ásélì. 44 Ásélì ní ọmọkùnrin mẹ́fà, orúkọ wọn ni Ásíríkámù, Bókérù, Íṣímáẹ́lì, Ṣearáyà, Ọbadáyà àti Hánánì. Gbogbo wọn ni ọmọ Ásélì.
10 Nígbà náà, àwọn Filísínì ń bá Ísírẹ́lì jà. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sá kúrò níwájú àwọn Filísínì, ọ̀pọ̀ lára wọn sì kú sórí Òkè Gíbóà.+ 2 Àwọn Filísínì sún mọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn Filísínì sì pa Jónátánì, Ábínádábù àti Maliki-ṣúà,+ àwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù. 3 Ìjà náà le mọ́ Sọ́ọ̀lù, ọwọ́ àwọn tafàtafà+ bà á, wọ́n sì dá ọgbẹ́ sí i lára. 4 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi ní àgúnyọ, kí àwọn aláìdádọ̀dọ́* yìí má bàa wá hùwà ìkà+ sí mi.”* Àmọ́, ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ẹ̀rù bà á gan-an. Torí náà, Sọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lé e.+ 5 Nígbà tí ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra rí i pé Sọ́ọ̀lù ti kú, òun náà ṣubú lé idà tirẹ̀, ó sì kú. 6 Bí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe kú nìyẹn, tí gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ sì kú pa pọ̀.+ 7 Nígbà tí gbogbo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tó wà ní àfonífojì* rí i pé gbogbo èèyàn ti sá lọ àti pé Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ; lẹ́yìn náà, àwọn Filísínì wá, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.
8 Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn Filísínì wá bọ́ àwọn nǹkan tó wà lára àwọn tí wọ́n pa, wọ́n rí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ti kú sórí Òkè Gíbóà.+ 9 Wọ́n bọ́ àwọn nǹkan tó wà lára rẹ̀, wọ́n gé orí rẹ̀ kúrò, wọ́n gbé ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ sí gbogbo ilẹ̀ àwọn Filísínì pé kí wọ́n ròyìn rẹ̀ fún àwọn òrìṣà+ wọn àti àwọn èèyàn wọn. 10 Wọ́n wá gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sínú ilé* ọlọ́run wọn, wọ́n sì kan agbárí rẹ̀ mọ́ ilé Dágónì.+
11 Nígbà tí gbogbo àwọn ará Jábéṣì+ ní Gílíádì gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn Filísínì ṣe sí Sọ́ọ̀lù,+ 12 gbogbo àwọn jagunjagun gbéra, wọ́n sì gbé òkú Sọ́ọ̀lù àti òkú àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n gbé wọn wá sí Jábéṣì, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi ńlá ní Jábéṣì,+ wọ́n sì fi ọjọ́ méje gbààwẹ̀.
13 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe kú nìyẹn nítorí ìwà àìṣòótọ́ tó hù sí Jèhófà torí pé kò ṣe ohun tí Jèhófà+ sọ àti pé ó lọ wádìí lọ́dọ̀ abẹ́mìílò+ 14 dípò kó wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà. Torí náà, Ó pa á, ó sì gbé ìjọba náà fún Dáfídì ọmọ Jésè.+
11 Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì,+ wọ́n sì sọ pé: “Wò ó! Ẹ̀jẹ̀* kan náà ni wá.+ 2 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí Sọ́ọ̀lù jẹ́ ọba, ìwọ lò ń kó Ísírẹ́lì jáde ogun.*+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì sọ fún ọ pé: ‘Ìwọ́ ni wàá máa bójú tó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí àgùntàn, wàá sì di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’”+ 3 Nítorí náà, gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ ọba ní Hébúrónì, Dáfídì sì bá wọn dá májẹ̀mú ní Hébúrónì níwájú Jèhófà. Lẹ́yìn náà, wọ́n fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Sámúẹ́lì sọ.+
4 Lẹ́yìn náà, Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì jáde lọ sí Jerúsálẹ́mù, ìyẹn ní Jébúsì,+ ilẹ̀ tí àwọn ará Jébúsì+ ń gbé. 5 Àwọn tó ń gbé ní Jébúsì pẹ̀gàn Dáfídì pé: “O ò ní wọ ibí yìí!”+ Síbẹ̀, Dáfídì gba ibi ààbò Síónì,+ èyí tó wá di Ìlú Dáfídì.+ 6 Torí náà, Dáfídì sọ pé: “Ẹni tó bá kọ́kọ́ gbéjà ko àwọn ará Jébúsì ló máa di balógun* àti ìjòyè.” Jóábù+ ọmọ Seruáyà ló kọ́kọ́ lọ, ó sì di balógun. 7 Nígbà náà, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibi ààbò, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Ìlú Dáfídì. 8 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìlú náà yí ká láti Òkìtì* títí dé àyíká rẹ̀, Jóábù sì tún apá tó kù lára ìlú náà kọ́. 9 Bí agbára Dáfídì ṣe ń pọ̀ sí i+ nìyẹn, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
10 Àwọn tó jẹ́ olórí àwọn jagunjagun Dáfídì tó lákíkanjú nìyí, àwọn àti gbogbo Ísírẹ́lì ló tì í lẹ́yìn nínú ìjọba rẹ̀, kí wọ́n lè fi í jọba gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Ísírẹ́lì.+ 11 Orúkọ àwọn jagunjagun Dáfídì tó lákíkanjú nìyí: Jáṣóbéámù+ ọmọ ará Hákímónì, olórí àwọn mẹ́ta náà.+ Ìgbà kan wà tó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin.+ 12 Ẹni tí ó tẹ̀ lé e ni Élíásárì+ ọmọ Dódò ọmọ Áhóhì.+ Ó wà lára àwọn jagunjagun mẹ́ta tó lákíkanjú. 13 Ó wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pasi-dámímù,+ níbi tí àwọn Filísínì kóra jọ sí láti jagun. Lákòókò náà, ilẹ̀ kan wà tí ọkà bálì pọ̀ sí, àwọn èèyàn sì ti sá lọ nítorí àwọn Filísínì. 14 Àmọ́ ó dúró ní àárín ilẹ̀ náà, kò jẹ́ kí wọ́n gbà á, ó sì ń pa àwọn Filísínì náà, tó fi jẹ́ pé Jèhófà mú kí ìṣẹ́gun*+ ńlá wáyé.
15 Mẹ́ta lára ọgbọ̀n (30) ọkùnrin tó jẹ́ olórí lọ sí ibi àpáta lọ́dọ̀ Dáfídì ní ihò àpáta Ádúlámù,+ lákòókò yìí, àwùjọ àwọn ọmọ ogun Filísínì kan pàgọ́ sí Àfonífojì* Réfáímù.+ 16 Nígbà yẹn, Dáfídì wà ní ibi ààbò, àwùjọ ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó sì wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. 17 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ ohun tó ń wù ú, ó ní: “Ì bá dára ká ní mo lè rí omi mu láti inú kòtò omi tó wà ní ẹnubodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù!”+ 18 Ni àwọn mẹ́ta náà bá fipá wọnú ibùdó àwọn Filísínì, wọ́n fa omi láti inú kòtò omi tó wà ní ẹnubodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọ́n sì gbé e wá fún Dáfídì; àmọ́ Dáfídì kọ̀, kò mu ún, ńṣe ló dà á jáde fún Jèhófà. 19 Ó sọ pé: “Ọlọ́run ò gbọ́dọ̀ gbọ́ pé mo ṣe nǹkan yìí! Ṣé ó yẹ kí n mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tó fẹ̀mí*+ ara wọn wewu yìí? Nítorí ẹ̀mí* wọn ni wọ́n fi wewu kí wọ́n lè gbé e wá.” Torí náà, ó kọ̀, kò mu ún. Àwọn ohun tí àwọn jagunjagun rẹ̀ mẹ́ta tó lákíkanjú ṣe nìyẹn.
20 Ábíṣáì+ ẹ̀gbọ́n Jóábù+ di olórí àwọn mẹ́ta míì; ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin, òun náà sì lórúkọ bí àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́.+ 21 Láàárín àwọn mẹ́ta kejì, òun ló ta yọ jù, òun sì ni olórí wọn; síbẹ̀ kò wọ ẹgbẹ́ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́.
22 Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà jẹ́ akíkanjú ọkùnrin* tó gbé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe ní Kábúséélì.+ Ó pa àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Áríélì ará Móábù bí, ó wọ inú kòtò omi lọ́jọ́ kan tí yìnyín bolẹ̀, ó sì pa kìnnìún.+ 23 Ó tún mú ọkùnrin ará Íjíbítì kan tó tóbi fàkìàfakia balẹ̀ tó ga ní ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.*+ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kọ̀ tó wà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà dà bí ọ̀pá àwọn ahunṣọ,*+ ó fi ọ̀pá bá a jà, ó já ọ̀kọ̀ náà gbà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ òun fúnra rẹ̀ pa á.+ 24 Àwọn ohun tí Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà ṣe nìyẹn, ó lórúkọ bí àwọn akíkanjú jagunjagun mẹ́ta náà. 25 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ta yọ ju àwọn ọgbọ̀n (30) náà, kò wọ ẹgbẹ́ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́.+ Àmọ́ Dáfídì yàn án ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
26 Àwọn jagunjagun tó lákíkanjú nínú ẹgbẹ́ ológun ni Ásáhélì+ arákùnrin Jóábù, Élíhánánì ọmọ Dódò ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ 27 Ṣámótì ará Hárórù, Hélésì tó jẹ́ Pélónì, 28 Írà+ ọmọ Íkéṣì ará Tékóà, Abi-ésérì+ ọmọ Ánátótì, 29 Síbékáì+ ọmọ Húṣà, Íláì ọmọ Áhóhì, 30 Máháráì+ ará Nétófà, Hélédì+ ọmọ Báánà ará Nétófà, 31 Ítááì ọmọ Ríbáì ará Gíbíà ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì,+ Bẹnáyà ará Pírátónì, 32 Húráì tó wá láti àwọn àfonífojì Gááṣì,+ Ábíélì tó jẹ́ Ábátì, 33 Ásímáfẹ́tì ará Báhúrímù, Élíábà tó jẹ́ Ṣáálíbónì, 34 àwọn ọmọ Háṣémù tó jẹ́ Gísónì, Jónátánì ọmọ Ṣágéè tó jẹ́ Hárárì, 35 Áhíámù ọmọ Sákárì tó jẹ́ Hárárì, Élífálì ọmọ Úrì, 36 Héfà ọmọ Mékérà, Áhíjà tó jẹ́ Pélónì, 37 Hésírò ará Kámẹ́lì, Nááráì ọmọ Ésíbáì, 38 Jóẹ́lì arákùnrin Nátánì, Míbúhárì ọmọ Hágírì, 39 Sélékì ọmọ Ámónì, Náháráì ará Bérótì, tó ń bá Jóábù ọmọ Seruáyà gbé ìhámọ́ra; 40 Írà tó jẹ́ Ítírì, Gárébù tó jẹ́ Ítírì, 41 Ùráyà+ ọmọ Hétì, Sábádì ọmọ Áláì, 42 Ádínà ọmọ Ṣísà ọmọ Rúbẹ́nì, ọ̀kan lára olórí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti ọgbọ̀n (30) èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀; 43 Hánánì ọmọ Máákà, Jóṣáfátì tó jẹ́ Mítínì, 44 Úsíà ará Áṣítárótì, Ṣémà àti Jéélì, àwọn ọmọ Hótámù ará Áróérì; 45 Jédáélì ọmọ Ṣímúrì, Jóhà arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ Tísì; 46 Élíélì tó jẹ́ Máháfì, Jéríbáì àti Joṣafáyà àwọn ọmọ Élínáámù, Ítímà ọmọ Móábù; 47 Élíélì, Óbédì àti Jáásíélì ará Sóbà.
12 Àwọn tó wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Síkílágì+ nígbà tí kò lè rìn fàlàlà nítorí Sọ́ọ̀lù+ ọmọ Kíṣì nìyí, wọ́n wà lára àwọn jagunjagun tó lákíkanjú tó tì í lẹ́yìn lójú ogun.+ 2 Ọfà* wà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì lè fi ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì+ ta òkúta+ tàbí kí wọ́n fi ta ọfà látinú ọrun. Arákùnrin Sọ́ọ̀lù ni wọ́n, láti Bẹ́ńjámínì.+ 3 Áhíésérì àti Jóáṣì ni olórí, àwọn méjèèjì jẹ́ ọmọ Ṣémáà ará Gíbíà;+ Jésíélì àti Pélétì àwọn ọmọ Ásímáfẹ́tì,+ Bérákà, Jéhù ọmọ Ánátótì, 4 Iṣimáyà ará Gíbíónì,+ jagunjagun tó lákíkanjú láàárín àwọn ọgbọ̀n náà,+ òun sì ni olórí wọn; Jeremáyà, Jáhásíẹ́lì, Jóhánánì, Jósábádì ará Gédérà, 5 Élúsáì, Jérímótì, Bealáyà, Ṣemaráyà, Ṣẹfatáyà ọmọ Hárífù, 6 Ẹlikénà, Isiṣáyà, Ásárẹ́lì, Jóésà àti Jáṣóbéámù, àwọn ọmọ Kórà;+ 7 Jóélà àti Sebadáyà àwọn ọmọ Jéróhámù ará Gédórì.
8 Àwọn kan lára àwọn ọmọ Gádì lọ dara pọ̀ mọ́ Dáfídì ní ibi ààbò tó wà ní aginjù;+ jagunjagun tó lákíkanjú ni wọ́n, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ti kọ́ṣẹ́ ogun, wọ́n dúró wámúwámú, wọ́n mú apata ńlá àti aṣóró dání, ojú wọn dà bíi ti kìnnìún, ẹsẹ̀ wọn sì yá nílẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín lórí òkè. 9 Ésérì ni olórí, Ọbadáyà ìkejì, Élíábù ìkẹta, 10 Míṣímánà ìkẹrin, Jeremáyà ìkarùn-ún, 11 Átáì ìkẹfà, Élíélì ìkeje, 12 Jóhánánì ìkẹjọ, Élísábádì ìkẹsàn-án, 13 Jeremáyà ìkẹwàá, Makibánáì ìkọkànlá. 14 Àwọn ni àwọn ọmọ Gádì,+ àwọn olórí ọmọ ogun. Ẹni tó kéré jù lè kápá ọgọ́rùn-ún (100) ọmọ ogun, ẹni tó sì lágbára jù lè kápá ẹgbẹ̀rún (1,000).+ 15 Àwọn ọkùnrin yìí ló sọdá Jọ́dánì ní oṣù kìíní nígbà tí ó kún bo bèbè rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tó ń gbé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ sápá ìlà oòrùn àti sápá ìwọ̀ oòrùn.
16 Àwọn kan lára àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì àti Júdà tún wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní ibi ààbò+ tó wà. 17 Ni Dáfídì bá jáde sí wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Tó bá jẹ́ pé àlàáfíà ni ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi kí ẹ lè ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi á ṣọ̀kan pẹ̀lú tiyín. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé kí ẹ lè fi mí lé ọ̀tá mi lọ́wọ́ nígbà tó jẹ́ pé mi ò ṣe ohun tí kò dáa, kí Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa rí sí i, kí ó sì ṣèdájọ́.”+ 18 Ìgbà náà ni ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé Ámásáì,*+ olórí ọgbọ̀n ọmọ ogun, ó ní:
“Tìrẹ ni wá, Dáfídì, ọ̀dọ̀ rẹ sì ni a wà, ìwọ ọmọ Jésè.+
Àlàáfíà, àlàáfíà fún ọ, àlàáfíà fún ẹni tó ń ràn ọ́ lọ́wọ́,
Nítorí Ọlọ́run rẹ ń ràn ọ́ lọ́wọ́.”+
Torí náà, Dáfídì gbà wọ́n, ó sì yàn wọ́n pé kí wọ́n wà lára àwọn olórí ọmọ ogun.
19 Àwọn kan lára ẹ̀yà Mánásè náà sá wá sọ́dọ̀ Dáfídì nígbà tó tẹ̀ lé àwọn Filísínì láti wá bá Sọ́ọ̀lù jà. Àmọ́ kò lè ran àwọn Filísínì lọ́wọ́, torí lẹ́yìn tí wọ́n gbàmọ̀ràn, àwọn alákòóso Filísínì+ ní kó pa dà, wọ́n ní: “Ó máa sá lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù olúwa rẹ̀, ẹ̀mí wa ló sì máa lọ sí i.”+ 20 Nígbà tó lọ sí Síkílágì,+ àwọn tó sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ látinú ẹ̀yà Mánásè ni: Ádínáhì, Jósábádì, Jédáélì, Máíkẹ́lì, Jósábádì, Élíhù àti Sílétáì, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè.+ 21 Wọ́n ran Dáfídì lọ́wọ́ láti gbéjà ko àwọn jàǹdùkú* nítorí gbogbo wọn jẹ́ alágbára, wọ́n nígboyà,+ wọ́n sì wá di olórí àwọn ọmọ ogun. 22 Ojoojúmọ́ ni àwọn èèyàn ń wá sọ́dọ̀ Dáfídì+ láti ràn án lọ́wọ́, títí ibẹ̀ fi di ibùdó tí ó tóbi bí ibùdó Ọlọ́run.+
23 Iye àwọn olórí ọmọ ogun tó ti gbára dì tó wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì+ láti fi í jọba ní ipò Sọ́ọ̀lù nìyí gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Jèhófà pa.+ 24 Àwọn èèyàn Júdà tó ń gbé apata ńlá àti aṣóró jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (6,800) ọmọ ogun tó ti gbára dì fún ogun. 25 Lára àwọn ọmọ Síméónì, àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ alágbára, tí wọ́n sì nígboyà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje ó lé ọgọ́rùn-ún (7,100).
26 Lára àwọn ọmọ Léfì, ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (4,600). 27 Jèhóádà+ ni aṣáájú àwọn ọmọ Áárónì,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje (3,700) ló sì wà pẹ̀lú rẹ̀ 28 àti Sádókù,+ ọ̀dọ́kùnrin kan tó lágbára, tó sì nígboyà pẹ̀lú àwọn olórí méjìlélógún (22) láti agbo ilé bàbá rẹ̀.
29 Lára àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, àwọn arákùnrin Sọ́ọ̀lù, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000),+ tí èyí tó pọ̀ jù lára wọn sì ti ń ṣọ́ ilé Sọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀. 30 Lára àwọn ọmọ Éfúrémù, ọ̀kẹ́ kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (20,800) alágbára àti onígboyà ọkùnrin ló jẹ́ olókìkí ní agbo ilé bàbá wọn.
31 Lára ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) ni a yan orúkọ wọn pé kí wọ́n wá fi Dáfídì jọba. 32 Lára àwọn ọmọ Ísákà, àwọn tó mọ ohun tó yẹ ní àkókò tó yẹ, tí wọ́n sì mọ ohun tó yẹ kí Ísírẹ́lì ṣe, igba (200) lára àwọn olórí wọn ló wà níbẹ̀, gbogbo àwọn arákùnrin wọn sì wà lábẹ́ àṣẹ wọn. 33 Lára Sébúlúnì, ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ (50,000) ọkùnrin ló wà tó lè ṣiṣẹ́ ogun, wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ pẹ̀lú ohun ìjà tí wọ́n fi ń jagun, gbogbo wọn dara pọ̀ mọ́ Dáfídì, wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i délẹ̀.* 34 Lára Náfútálì, ẹgbẹ̀rún (1,000) àwọn olórí ló wà, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógójì (37,000) ló sì wà pẹ̀lú wọn tí wọ́n gbé apata ńlá àti ọ̀kọ̀ dání. 35 Lára àwọn ọmọ Dánì, àwọn tó ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ fún ogun jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (28,600). 36 Lára Áṣérì, àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ogun láti máa jáde lọ́wọ̀ọ̀wọ́ fún ogun jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì (40,000).
37 Láti òdìkejì Jọ́dánì,+ lára àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ọmọ ogun ló wà, tí wọ́n ní oríṣiríṣi àwọn ohun ìjà tí wọ́n fi ń jagun. 38 Gbogbo wọn jẹ́ ọkùnrin ogun, tí wọ́n jọ máa ń kóra jọ sojú ogun; gbogbo ọkàn ni wọ́n fi wá sí Hébúrónì láti fi Dáfídì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, bákan náà, gbogbo ìyókù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló fohùn ṣọ̀kan pé àwọn máa* fi Dáfídì jọba.+ 39 Wọ́n fi ọjọ́ mẹ́ta wà níbẹ̀ pẹ̀lú Dáfídì, wọ́n ń jẹ wọ́n sì ń mu, nítorí àwọn arákùnrin wọn ti pèsè nǹkan sílẹ̀ dè wọ́n. 40 Bákan náà, àwọn tó wà nítòsí wọn, títí kan àwọn tó wà ní ilẹ̀ Ísákà, Sébúlúnì àti Náfútálì fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ràkúnmí, ìbaaka àti màlúù gbé oúnjẹ wá, ìyẹn àwọn ohun tí wọ́n fi ìyẹ̀fun ṣe, ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ àti ìṣù àjàrà gbígbẹ, wáìnì, òróró àti màlúù pẹ̀lú àgùntàn tó pọ̀ gan-an, torí pé ìdùnnú ṣubú layọ̀ ní Ísírẹ́lì.
13 Dáfídì fọ̀rọ̀ lọ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún pẹ̀lú gbogbo àwọn aṣáájú.+ 2 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì pé: “Tí ó bá dára lójú yín tí Jèhófà Ọlọ́run wa sì fọwọ́ sí i, ẹ jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí àwọn arákùnrin wa tó kù ní gbogbo agbègbè Ísírẹ́lì àti sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú+ wọn pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko wọn, kí wọ́n lè wá dara pọ̀ mọ́ wa. 3 Kí a sì gbé Àpótí+ Ọlọ́run wa pa dà.” Nítorí wọn kò bójú tó o nígbà ayé Sọ́ọ̀lù.+ 4 Gbogbo ìjọ náà fara mọ́ ọn pé àwọn á ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó tọ́ lójú gbogbo àwọn èèyàn náà. 5 Torí náà, Dáfídì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ láti odò* Íjíbítì títí dé Lebo-hámátì,*+ kí wọ́n lè gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá láti Kiriati-jéárímù.+
6 Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì lọ sí Báálà,+ sí Kiriati-jéárímù ti Júdà, kí wọ́n lè gbé Àpótí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ wá láti ibẹ̀, ẹni tó ń jókòó lórí* àwọn kérúbù,+ ibi tí a ti ń ké pe orúkọ rẹ̀. 7 Àmọ́, wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sórí kẹ̀kẹ́ tuntun,+ wọ́n gbé e wá láti ilé Ábínádábù. Úsà àti Áhíò sì ń darí kẹ̀kẹ́ náà.+ 8 Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì ń ṣe ayẹyẹ níwájú Ọlọ́run tòótọ́ tọkàntara pẹ̀lú orin, háàpù, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ìlù tanboríìnì+ àti síńbálì*+ pẹ̀lú kàkàkí.+ 9 Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Kídónì, Úsà na ọwọ́ rẹ̀, ó sì gbá Àpótí náà mú, torí màlúù náà mú kí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dojú dé. 10 Ni ìbínú Jèhófà bá ru sí Úsà, Ó pa á nítorí pé ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì gbá Àpótí+ náà mú, torí náà, ó kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.+ 11 Àmọ́ inú bí Dáfídì* nítorí pé ìbínú Jèhófà ru sí Úsà; wọ́n sì wá ń pe ibẹ̀ ní Peresi-úsà* títí di òní yìí.
12 Torí náà, ẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ ba Dáfídì ní ọjọ́ yẹn, ó sì sọ pé: “Ṣé ọ̀dọ̀ mi ló yẹ kí n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá?”+ 13 Dáfídì kò gbé Àpótí náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì, àmọ́ ó ní kí wọ́n gbé e lọ sí ilé Obedi-édómù ará Gátì. 14 Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sì wà ní agbo ilé Obedi-édómù, oṣù mẹ́ta ló fi wà ní ilé rẹ̀, Jèhófà sì ń bù kún agbo ilé Obedi-édómù àti gbogbo ohun tó ní.+
14 Hírámù+ ọba Tírè rán àwọn òjíṣẹ́ sí Dáfídì, ó kó igi kédárì ránṣẹ́, ó tún rán àwọn oníṣẹ́ òkúta* àti àwọn oníṣẹ́ igi láti kọ́ ilé* fún un.+ 2 Dáfídì wá mọ̀ pé Jèhófà ti fìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì,+ torí pé Ó ti gbé ìjọba Dáfídì ga nítorí àwọn èèyàn Rẹ̀ Ísírẹ́lì.+
3 Dáfídì fẹ́ ìyàwó sí i+ ní Jerúsálẹ́mù, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin púpọ̀ sí i.+ 4 Orúkọ àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún un ní Jerúsálẹ́mù+ nìyí: Ṣámúà, Ṣóbábù, Nátánì,+ Sólómọ́nì,+ 5 Íbárì, Élíṣúà, Élípélétì, 6 Nógà, Néfégì, Jáfíà, 7 Élíṣámà, Béélíádà àti Élífélétì.
8 Nígbà tí àwọn Filísínì gbọ́ pé wọ́n ti fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì,+ gbogbo àwọn Filísínì bẹ̀rẹ̀ sí í wá Dáfídì.+ Bí Dáfídì ṣe gbọ́ báyìí, ó lọ gbéjà kò wọ́n. 9 Ìgbà náà ni àwọn Filísínì wọlé wá, wọ́n sì ń kó nǹkan àwọn èèyàn ní Àfonífojì* Réfáímù.+ 10 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé: “Ṣé kí n lọ gbéjà ko àwọn Filísínì? Ṣé wàá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Ni Jèhófà bá sọ fún un pé: “Lọ, ó dájú pé màá fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”+ 11 Torí náà, Dáfídì lọ sí Baali-pérásímù,+ ó sì pa wọ́n níbẹ̀. Dáfídì wá sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ ti tipasẹ̀ ọwọ́ mi ya lu àwọn ọ̀tá mi, bí ìgbà tí omi bá ya lu nǹkan.” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Baali-pérásímù.* 12 Àwọn Filísínì fi àwọn ọlọ́run wọn sílẹ̀ níbẹ̀, a sì dáná sun+ wọ́n bí Dáfídì ṣe pa á láṣẹ.
13 Nígbà tó yá, àwọn Filísínì tún wá kó nǹkan àwọn èèyàn ní àfonífojì*+ náà. 14 Dáfídì tún wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un pé: “Má ṣe dojú kọ wọ́n ní tààràtà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yìn ni kí o gbà yọ sí wọn, kí o sì wá dojú kọ wọ́n níwájú àwọn igi bákà.+ 15 Tí o bá ti gbọ́ ìró tó ń dún bí ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi bákà, kí o dojú ìjà kọ wọ́n, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ yóò ti lọ ṣáájú rẹ láti ṣá àwọn ọmọ ogun Filísínì balẹ̀.”+ 16 Torí náà, Dáfídì ṣe ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́,+ wọ́n sì pa àwọn ọmọ ogun Filísínì láti Gíbíónì títí dé Gésérì.+ 17 Òkìkí Dáfídì kàn dé gbogbo àwọn ilẹ̀ náà, Jèhófà sì mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa bẹ̀rù rẹ̀.+
15 Dáfídì ń kọ́ àwọn ilé fún ara rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì, ó ṣètò ibì kan fún Àpótí Ọlọ́run tòótọ́, ó sì pa àgọ́ fún un.+ 2 Ìgbà náà ni Dáfídì sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ àfi àwọn ọmọ Léfì, nítorí àwọn ni Jèhófà yàn láti máa gbé Àpótí Jèhófà àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún òun nígbà gbogbo.”+ 3 Lẹ́yìn náà, Dáfídì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ sí Jerúsálẹ́mù láti gbé Àpótí Jèhófà wá sí ibi tí ó ti ṣètò sílẹ̀ fún un.+
4 Dáfídì kó àtọmọdọ́mọ Áárónì+ àti ti Léfì+ jọ: 5 látinú àwọn ọmọ Kóhátì, Úríélì ni olórí àti ọgọ́fà (120) àwọn arákùnrin rẹ̀; 6 látinú àwọn ọmọ Mérárì, Ásáyà+ ni olórí àti igba ó lé ogun (220) àwọn arákùnrin rẹ̀; 7 látinú àwọn ọmọ Gẹ́ṣómù, Jóẹ́lì+ ni olórí àti àádóje (130) àwọn arákùnrin rẹ̀; 8 látinú àwọn ọmọ Élísáfánì,+ Ṣemáyà ni olórí àti igba (200) àwọn arákùnrin rẹ̀; 9 látinú àwọn ọmọ Hébúrónì, Élíélì ni olórí àti ọgọ́rin (80) àwọn arákùnrin rẹ̀; 10 látinú àwọn ọmọ Úsíélì,+ Ámínádábù ni olórí àti àádọ́fà ó lé méjì (112) àwọn arákùnrin rẹ̀. 11 Yàtọ̀ síyẹn, Dáfídì pe àlùfáà Sádókù+ àti àlùfáà Ábíátárì+ àti àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn Úríélì, Ásáyà, Jóẹ́lì, Ṣemáyà, Élíélì àti Ámínádábù, 12 ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ni olórí agbo ilé àwọn ọmọ Léfì. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ̀yin àti àwọn arákùnrin yín, kí ẹ sì gbé Àpótí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wá sí ibi tí mo ti ṣètò sílẹ̀ fún un. 13 Nítorí ẹ̀yin kọ́ lẹ gbé e nígbà àkọ́kọ́+ ni ìbínú Jèhófà Ọlọ́run ṣe ru sí wa,+ torí pé a ò wádìí bó ṣe yẹ ká gbé e.”+ 14 Nítorí náà, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé Àpótí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wá.
15 Nígbà náà, àwọn ọmọ Léfì fi àwọn ọ̀pá+ gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ lé èjìká wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Mósè pa látọ̀dọ̀ Jèhófà. 16 Dáfídì wá sọ fún àwọn olórí ọmọ Léfì pé kí wọ́n yan àwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ akọrin láti máa fi ayọ̀ kọrin, kí wọ́n máa lo àwọn ohun ìkọrin, ìyẹn àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ pẹ̀lú síńbálì.*+
17 Torí náà, àwọn ọmọ Léfì yan Hémánì+ ọmọ Jóẹ́lì, lára àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n yan Ásáfù+ ọmọ Berekáyà, lára àwọn ọmọ Mérárì tí wọ́n jẹ́ arákùnrin wọn, wọ́n yan Étánì+ ọmọ Kuṣáyà. 18 Àwọn arákùnrin wọn tó wà pẹ̀lú wọn tí wọ́n jẹ́ àwùjọ kejì+ ni: Sekaráyà, Bẹ́nì, Jáásíẹ́lì, Ṣẹ́mírámótì, Jéhíélì, Únì, Élíábù, Bẹnáyà, Maaseáyà, Matitáyà, Élíféléhù, Mikinéáyà pẹ̀lú Obedi-édómù àti Jéélì tí wọ́n jẹ́ aṣọ́bodè. 19 Hémánì,+ Ásáfù+ àti Étánì tí wọ́n jẹ́ akọrin ni wọ́n á máa fi síńbálì bàbà+ kọrin; 20 Sekaráyà, Ásíẹ́lì, Ṣẹ́mírámótì, Jéhíélì, Únì, Élíábù, Maaseáyà àti Bẹnáyà ni wọ́n ń ta ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín tó ń dún bí Álámótì.*+ 21 Matitáyà,+ Élíféléhù, Mikinéáyà, Obedi-édómù, Jéélì àti Asasáyà ń ta háàpù tó ń dún bíi Ṣẹ́mínítì,*+ àwọn ni olùdarí. 22 Kenanáyà+ olórí àwọn ọmọ Léfì ló ń bójú tó gbígbé ẹrù, torí pé ọ̀jáfáfá ni, 23 Berekáyà àti Ẹlikénà ni aṣọ́bodè tó ń ṣọ́ Àpótí. 24 Àwọn àlùfáà, ìyẹn Ṣebanáyà, Jóṣáfátì, Nétánélì, Ámásáì, Sekaráyà, Bẹnáyà àti Élíésérì ń fun kàkàkí kíkankíkan níwájú Àpótí Ọlọ́run tòótọ́,+ Obedi-édómù àti Jeháyà sì ni aṣọ́bodè tó ń ṣọ́ Àpótí.
25 Nígbà náà, Dáfídì àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún jọ ń rìn lọ tayọ̀tayọ̀+ láti gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà wá láti ilé Obedi-édómù.+ 26 Torí pé Ọlọ́run tòótọ́ ran àwọn ọmọ Léfì tó ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà lọ́wọ́, wọ́n fi akọ ọmọ màlúù méje àti àgbò méje+ rúbọ. 27 Dáfídì wọ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí wọ́n fi aṣọ àtàtà ṣe, bákan náà ni gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó gbé Àpótí náà ṣe múra, àwọn akọrin àti Kenanáyà olórí tó ń bójú tó gbígbé ẹ̀rù àti àwọn tó ń kọrin; Dáfídì sì tún wọ éfódì+ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀* ṣe. 28 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà bọ̀ pẹ̀lú igbe ayọ̀+ àti pẹ̀lú ìró ìwo àti kàkàkí+ pẹ̀lú síńbálì, wọ́n sì ń fi àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ kọrin sókè.
29 Àmọ́ nígbà tí àpótí májẹ̀mú Jèhófà wọ Ìlú Dáfídì,+ Míkálì,+ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù, bojú wolẹ̀ lójú fèrèsé,* ó rí Ọba Dáfídì tó ń jó sọ́tùn-ún sósì, tó sì ń ṣayẹyẹ; ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í pẹ̀gàn rẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀.+
16 Torí náà, wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wọlé, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sí àyè rẹ̀ nínú àgọ́ tí Dáfídì pa fún un;+ wọ́n mú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá síwájú Ọlọ́run tòótọ́.+ 2 Nígbà tí Dáfídì parí rírú àwọn ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ náà, ó fi orúkọ Jèhófà súre fún àwọn èèyàn náà. 3 Láfikún sí i, ó pín ìṣù búrẹ́dì ribiti àti ìṣù èso déètì àti ìṣù àjàrà gbígbẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó fún kálukú wọn lọ́kùnrin lóbìnrin. 4 Lẹ́yìn náà, ó yan lára àwọn ọmọ Léfì láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú Àpótí Jèhófà,+ kí wọ́n máa bọlá fún* Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, kí wọ́n sì máa yìn ín. 5 Ásáfù+ ni olórí, Sekaráyà ni igbá kejì rẹ̀; Jéélì, Ṣẹ́mírámótì, Jéhíélì, Matitáyà, Élíábù, Bẹnáyà, Obedi-édómù àti Jéélì+ ń ta àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù;+ Ásáfù ń lo síńbálì,*+ 6 Bẹnáyà àti Jáhásíẹ́lì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà sì ń fun kàkàkí déédéé níwájú àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́.
7 Ọjọ́ yẹn ni Dáfídì kọ́kọ́ ṣàkọsílẹ̀ orin ìdúpẹ́ kan fún Jèhófà, ó sì ní kí Ásáfù+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kọ ọ́ pé:
10 Ẹ máa fi orúkọ mímọ́+ rẹ̀ yangàn.
Kí ọkàn àwọn tó ń wá Jèhófà máa yọ̀.+
11 Ẹ máa wá Jèhófà+ àti agbára rẹ̀.
Ẹ máa wá ojú rẹ̀* nígbà gbogbo.+
12 Ẹ máa rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tó ti ṣe,+
Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ tó kéde,
13 Ẹ̀yin ọmọ* Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀,+
Ẹ̀yin ọmọ Jékọ́bù, ẹ̀yin àyànfẹ́ rẹ̀.+
14 Òun ni Jèhófà Ọlọ́run wa.+
Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ kárí ayé.+
15 Ẹ máa rántí májẹ̀mú rẹ̀ títí láé,
Ẹ máa rántí ìlérí tó ṣe* títí dé ẹgbẹ̀rún ìran,+
16 Májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá+
Àti ìbúra rẹ̀ fún Ísákì,+
17 Èyí tó gbé kalẹ̀ bí ìlànà fún Jékọ́bù+
Àti bíi májẹ̀mú tó wà títí láé fún Ísírẹ́lì,
18 Ó ní, ‘Màá fún ọ ní ilẹ̀ Kénáánì+
Bí ogún tí a pín fún yín.’+
19 Èyí jẹ́ nígbà tí ẹ kéré níye,
Bẹ́ẹ̀ ni, tí ẹ kéré níye gan-an, tí ẹ sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà.+
20 Wọ́n ń rìn kiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,
Láti ọ̀dọ̀ ìjọba kan dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn míì.+
21 Kò gbà kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,+
Ṣùgbọ́n nítorí wọn, ó bá àwọn ọba wí,+
22 Ó ní, ‘Ẹ má fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi,
Ẹ má sì ṣe ohun búburú sí àwọn wòlíì mi.’+
23 Ẹ kọrin sí Jèhófà, gbogbo ayé!
Ẹ kéde ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́!+
24 Ẹ máa kéde ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,
Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo àwọn èèyàn.
25 Nítorí pé Jèhófà tóbi, òun sì ni ìyìn yẹ jù lọ.
Ó yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ.+
28 Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i, ẹ̀yin ìdílé gbogbo ayé,
Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i nítorí ògo àti agbára rẹ̀.+
Ẹ forí balẹ̀ fún* Jèhófà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ mímọ́.*+
30 Kí jìnnìjìnnì bá yín níwájú rẹ̀, gbogbo ayé!
Ayé* fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in; kò ṣeé ṣí nípò.*+
32 Kí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ dún bí ààrá;
Kí àwọn pápá àti gbogbo ohun tó wà lórí wọn máa dunnú.
33 Ní àkókò kan náà, kí àwọn igi igbó kígbe ayọ̀ níwájú Jèhófà,
Nítorí ó ń bọ̀ wá* ṣèdájọ́ ayé.
35 Ẹ sọ pé, ‘Gbà wá, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà wa,+
Kó wa jọ, kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
Ká lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ+
Gbogbo èèyàn sì sọ pé, “Àmín!”* wọ́n sì yin Jèhófà.
37 Lẹ́yìn náà, Dáfídì fi Ásáfù+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú àpótí májẹ̀mú Jèhófà kí wọ́n lè máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú Àpótí+ nígbà gbogbo, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ojoojúmọ́.+ 38 Obedi-édómù àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn méjìdínláàádọ́rin (68) àti Obedi-édómù ọmọ Jédútúnì pẹ̀lú Hósà jẹ́ aṣọ́bodè; 39 Àlùfáà Sádókù+ àti àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ àlùfáà wà níwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà ní ibi gíga tó wà ní Gíbíónì+ 40 láti máa rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà lórí pẹpẹ ẹbọ sísun déédéé, ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ àti láti máa ṣe gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Jèhófà tó pa láṣẹ fún Ísírẹ́lì.+ 41 Àwọn tó wà pẹ̀lú wọn ni Hémánì àti Jédútúnì+ pẹ̀lú ìyókù àwọn ọkùnrin tí a fi orúkọ yàn láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà,+ nítorí “ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé”;+ 42 Hémánì+ àti Jédútúnì wà pẹ̀lú wọn láti máa fun kàkàkí, láti máa lo síńbálì àti àwọn ohun ìkọrin tí a fi ń yin* Ọlọ́run tòótọ́; àwọn ọmọ Jédútúnì+ sì wà ní ẹnubodè. 43 Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn lọ sí ilé wọn, Dáfídì sì lọ súre fún agbo ilé rẹ̀.
17 Gbàrà tí Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé inú ilé* rẹ̀, ó sọ fún wòlíì Nátánì+ pé: “Mò ń gbé inú ilé tí wọ́n fi igi kédárì+ kọ́ nígbà tí àpótí májẹ̀mú Jèhófà wà lábẹ́ àwọn aṣọ àgọ́.”+ 2 Nátánì dá Dáfídì lóhùn pé: “Ṣe ohunkóhun tó wà lọ́kàn rẹ, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú rẹ.”
3 Lóru ọjọ́ yẹn, Ọlọ́run bá Nátánì sọ̀rọ̀, ó ní: 4 “Lọ sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ìwọ kọ́ ló máa kọ́ ilé tí màá gbé fún mi.+ 5 Nítorí mi ò gbé inú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Ísírẹ́lì jáde títí di òní yìí, àmọ́ mò ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti látinú àgọ́ ìjọsìn kan dé òmíràn.*+ 6 Ní gbogbo àkókò tí mò ń bá gbogbo Ísírẹ́lì rìn, ṣé mo fìgbà kankan sọ fún ọ̀kan lára àwọn onídàájọ́ tí mo yàn láti máa bójú tó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí àgùntàn, pé, ‘Kí ló dé tí ẹ ò fi kọ́ ilé onígi kédárì fún mi?’”’
7 “Ní báyìí, sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo mú ọ láti ibi ìjẹko, pé kí o má da agbo ẹran mọ́, kí o lè wá di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+ 8 Màá wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí o bá lọ,+ màá sì mú* gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ;+ màá jẹ́ kí orúkọ rẹ lókìkí bí orúkọ àwọn ẹni ńlá tó wà láyé.+ 9 Màá yan ibì kan fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì, màá fìdí wọn kalẹ̀, wọ́n á sì máa gbé ibẹ̀ láìsì ìyọlẹ́nu mọ́; àwọn ẹni burúkú kò ní pọ́n wọn lójú* mọ́, bí wọ́n ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀,+ 10 láti ọjọ́ tí mo ti yan àwọn onídàájọ́ fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+ Màá ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.+ Wò ó, yàtọ̀ síyẹn, ó dájú pé, ‘Jèhófà yóò kọ́ ilé fún ọ.’*
11 “‘“Nígbà tí o bá kú, tí o sì lọ síbi tí àwọn baba ńlá rẹ wà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ,+ màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+ 12 Òun ló máa kọ́ ilé fún mi,+ màá sì fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.+ 13 Màá di bàbá rẹ̀, á sì di ọmọ mi.+ Mi ò ní mú ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kúrò lára rẹ̀+ bí mo ṣe mú un kúrò lára ẹni tó ṣáájú rẹ.+ 14 Màá mú kó dúró nínú ilé mi àti nínú ìjọba mi títí láé,+ ìtẹ́ rẹ̀ á sì wà títí láé.”’”+
15 Nátánì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí àti gbogbo ìran tó rí fún Dáfídì.
16 Ni Ọba Dáfídì bá wọlé, ó jókòó níwájú Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run, ta ni mí? Kí ni ilé mi sì já mọ́ tí o fi mú mi dé ibi tí mo dé yìí?+ 17 Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, ìwọ Ọlọ́run, o tún sọ nípa ilé ìránṣẹ́ rẹ títí lọ dé ọjọ́ iwájú tó jìnnà,+ o sì ṣíjú wò mí bíi pé ẹni tó yẹ ká túbọ̀ gbé ga* ni mí, Jèhófà Ọlọ́run. 18 Kí ni Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ tún lè sọ fún ọ nípa bí o ṣe bọlá fún mi, nígbà tí o sì mọ ìránṣẹ́ rẹ dáadáa?+ 19 Jèhófà, nítorí ìránṣẹ́ rẹ àti nítorí ohun tó wà lọ́kàn rẹ* ni o fi ṣe gbogbo àwọn ohun ńlá yìí, tí o sì tipa bẹ́ẹ̀ fi títóbi rẹ+ hàn. 20 Jèhófà, kò sí ẹni tó dà bí rẹ,+ kò sì sí Ọlọ́run kankan àfi ìwọ;+ gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́ jẹ́rìí sí i. 21 Orílẹ̀-èdè wo ní gbogbo ayé ló dà bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì?+ Ọlọ́run tòótọ́ lọ rà wọ́n pa dà nítorí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀.+ O ṣe orúkọ fún ara rẹ bí o ṣe ń ṣe àwọn ohun ńlá àti àwọn ohun àgbàyanu,+ tí o sì ń lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn èèyàn rẹ+ tí o rà pa dà láti Íjíbítì. 22 O sọ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì di àwọn èèyàn tí á máa jẹ́ tìrẹ títí lọ;+ ìwọ Jèhófà sì di Ọlọ́run wọn.+ 23 Ní báyìí, Jèhófà, jẹ́ kí ìlérí tí o ṣe nípa ìránṣẹ́ rẹ àti nípa ilé rẹ̀ ṣẹ títí láé, kí o sì ṣe ohun tí o ṣèlérí.+ 24 Kí orúkọ rẹ wà* títí láé, kí a sì máa gbé e ga,+ kí àwọn èèyàn lè sọ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ni Ọlọ́run tó ń ṣàkóso Ísírẹ́lì,’ kí ilé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ sì fìdí múlẹ̀ níwájú rẹ.+ 25 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run mi, ti fi han ìránṣẹ́ rẹ ìdí tí o fẹ́ fi kọ́ ilé fún un.* Ìdí nìyẹn tí ìránṣẹ́ rẹ fi ní ìgboyà láti gba àdúrà yìí sí ọ. 26 Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́, o sì ti ṣèlérí àwọn ohun rere yìí nípa ìránṣẹ́ rẹ. 27 Nítorí náà, jẹ́ kí ó dùn mọ́ ọ nínú láti bù kún ilé ìránṣẹ́ rẹ, sì jẹ́ kí ó máa wà títí láé níwájú rẹ, nítorí ìwọ, Jèhófà, ti bù kún un, ìbùkún á sì wà lórí rẹ̀ títí láé.”
18 Nígbà tó yá, Dáfídì ṣẹ́gun àwọn Filísínì, ó borí wọn, Dáfídì sì gba Gátì+ àti àwọn àrọko* rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Filísínì.+ 2 Lẹ́yìn náà, Dáfídì ṣẹ́gun Móábù,+ àwọn ọmọ Móábù wá di ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ń mú ìṣákọ́lẹ̀*+ wá.
3 Dáfídì ṣẹ́gun Hadadésà+ ọba Sóbà+ nítòsí Hámátì,+ bí ó ṣe ń lọ fìdí àkóso rẹ̀ múlẹ̀ ní odò Yúfírétì.+ 4 Dáfídì gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ ẹṣin, ẹgbẹ̀rún méje (7,000) agẹṣin àti ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn lọ́wọ́ rẹ̀.+ Dáfídì sì já iṣan ẹsẹ̀* gbogbo àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ogun, àmọ́ ó dá ọgọ́rùn-ún (100) lára àwọn ẹṣin náà sí.+ 5 Nígbà tí àwọn ará Síríà tó wà ní Damásíkù wá ran Hadadésà ọba Sóbà lọ́wọ́, Dáfídì pa ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) lára àwọn ará Síríà náà.+ 6 Lẹ́yìn náà, Dáfídì fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí Damásíkù ní Síríà, àwọn ará Síríà wá di ìránṣẹ́ Dáfídì, wọ́n sì ń mú ìṣákọ́lẹ̀* wá. Jèhófà sì ń jẹ́ kí Dáfídì ṣẹ́gun* ní ibikíbi tó bá lọ.+ 7 Láfikún sí i, Dáfídì gba àwọn apata* wúrà tó wà lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà, ó sì kó wọn wá sí Jerúsálẹ́mù. 8 Dáfídì kó bàbà tó pọ̀ gan-an láti Tíbátì àti Kúnì, àwọn ìlú Hadadésà. Òun ni Sólómọ́nì fi ṣe Òkun bàbà+ àti àwọn òpó pẹ̀lú àwọn nǹkan èlò bàbà.+
9 Nígbà tí Tóù ọba Hámátì gbọ́ pé Dáfídì ti ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadésà+ ọba Sóbà,+ 10 lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rán Hádórámù ọmọkùnrin rẹ̀ sí Ọba Dáfídì pé kí ó lọ béèrè àlàáfíà rẹ̀, kí ó sì bá a yọ̀ torí pé ó ti bá Hadadésà jà, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ (nítorí Hadadésà ti máa ń bá Tóù jà tẹ́lẹ̀), ó sì kó oríṣiríṣi ohun èlò wúrà, ohun èlò fàdákà àti ohun èlò bàbà wá. 11 Ọba Dáfídì yà wọ́n sí mímọ́ fún Jèhófà+ pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tó kó lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí: láti Édómù àti Móábù, látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ àwọn Filísínì+ àti àwọn ọmọ Ámálékì.+
12 Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà + pa ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) lára àwọn ọmọ Édómù ní Àfonífojì Iyọ̀.+ 13 Ó fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí Édómù, gbogbo àwọn ọmọ Édómù sì di ìránṣẹ́ Dáfídì.+ Jèhófà sì ń jẹ́ kí Dáfídì ṣẹ́gun* ní ibikíbi tó bá lọ.+ 14 Dáfídì ń jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì,+ ó ń dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó sì ń ṣe òdodo sí gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.+ 15 Jóábù ọmọ Seruáyà ni olórí àwọn ọmọ ogun,+ Jèhóṣáfátì+ ọmọ Áhílúdù sì ni akọ̀wé ìrántí, 16 Sádókù ọmọ Áhítúbù àti Áhímélékì ọmọ Ábíátárì ni àlùfáà, Ṣáfúṣà sì ni akọ̀wé. 17 Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà ni olórí àwọn Kérétì+ àti àwọn Pẹ́lẹ́tì.+ Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì ló sì wà ní ipò iwájú lẹ́yìn ọba.
19 Nígbà tó yá Náháṣì ọba àwọn ọmọ Ámónì kú, ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+ 2 Dáfídì bá sọ pé: “Màá fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀+ hàn sí Hánúnì ọmọ Náháṣì, nítorí bàbá rẹ̀ fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi.” Torí náà, Dáfídì rán àwọn òjíṣẹ́ láti lọ tù ú nínú nítorí bàbá rẹ̀ tó kú. Àmọ́ nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì dé ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì+ láti tu Hánúnì nínú, 3 àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Ámónì sọ fún Hánúnì pé: “Ṣé o rò pé torí kí Dáfídì lè bọlá fún bàbá rẹ ló ṣe rán àwọn olùtùnú sí ọ? Ǹjẹ́ kì í ṣe torí kó lè wo inú ìlú yìí fínnífínní, kó lé ọ kúrò lórí oyè, kí ó sì ṣe amí ilẹ̀ yìí ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi wá sọ́dọ̀ rẹ?” 4 Nítorí náà, Hánúnì mú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ó fá irun wọn,+ ó gé ẹ̀wù wọn ní ààbọ̀ dé ìdí, ó sì ní kí wọ́n máa lọ. 5 Nígbà tí wọ́n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọkùnrin náà fún Dáfídì, kíá ló rán àwọn míì lọ pàdé wọn, nítorí wọ́n ti dójú ti àwọn ọkùnrin náà gan-an; ọba sì sọ fún wọn pé: “Ẹ dúró sí Jẹ́ríkò+ títí irùngbọ̀n yín á fi hù pa dà, lẹ́yìn náà kí ẹ pa dà wálé.”
6 Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ámónì rí i pé àwọn ti di ẹni ìkórìíra lójú Dáfídì, torí náà, Hánúnì àti àwọn ọmọ Ámónì fi ẹgbẹ̀rún (1,000) tálẹ́ńtì* fàdákà ránṣẹ́ láti háyà àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn agẹṣin láti Mesopotámíà,* Aramu-máákà àti Sóbà.+ 7 Bí wọ́n ṣe háyà ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n (32,000) kẹ̀kẹ́ ẹṣin nìyẹn pẹ̀lú ọba Máákà àti àwọn èèyàn rẹ̀. Ìgbà náà ni wọ́n wá, wọ́n sì pàgọ́ síwájú Médébà.+ Àwọn ọmọ Ámónì kóra jọ láti àwọn ìlú wọn, wọ́n sì jáde wá jagun.
8 Nígbà tí Dáfídì gbọ́, ó rán Jóábù+ lọ àti gbogbo àwọn ọmọ ogun títí kan àwọn jagunjagun rẹ̀ tó lákíkanjú jù lọ.+ 9 Àwọn ọmọ Ámónì jáde lọ, wọ́n sì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ní àtiwọ ẹnubodè ìlú, àmọ́ àwọn ọba tó wá náà dúró sórí pápá.
10 Nígbà tí Jóábù rí i pé wọ́n ń gbé ogun bọ̀ níwájú àti lẹ́yìn, ó yan lára àwọn ọmọ ogun tó dára jù lọ ní Ísírẹ́lì, ó sì tò wọ́n lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti pàdé àwọn ará Síríà.+ 11 Ó fi àwọn tó kù lára àwọn ọkùnrin náà sábẹ́ àṣẹ* Ábíṣáì+ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, kí ó lè tò wọ́n lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti pàdé àwọn ọmọ Ámónì. 12 Ó wá sọ pé: “Tí ọwọ́ àwọn ará Síríà+ bá le jù fún mi, kí o wá gbà mí sílẹ̀; àmọ́ tí ọwọ́ àwọn ọmọ Ámónì bá le jù fún ọ, màá gbà ọ́ sílẹ̀. 13 Kí a jẹ́ alágbára, kí a sì ní ìgboyà+ nítorí àwọn èèyàn wa àti àwọn ìlú Ọlọ́run wa, Jèhófà yóò sì ṣe ohun tó dára ní ojú rẹ̀.”
14 Ìgbà náà ni Jóábù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ jáde lọ pàdé àwọn ará Síríà lójú ogun, wọ́n sì sá kúrò níwájú rẹ̀.+ 15 Nígbà tí àwọn ọmọ Ámónì rí i pé àwọn ará Síríà ti fẹsẹ̀ fẹ, àwọn náà sá kúrò níwájú Ábíṣáì ẹ̀gbọ́n rẹ̀, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Lẹ́yìn náà, Jóábù wá sí Jerúsálẹ́mù.
16 Nígbà tí àwọn ará Síríà rí i pé Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn, wọ́n rán àwọn òjíṣẹ́ láti pe àwọn ará Síríà tó wà ní agbègbè Odò*+ jọ, Ṣófákì olórí àwọn ọmọ ogun Hadadésà ló sì ń darí wọn.+
17 Nígbà tí wọ́n ròyìn fún Dáfídì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, ó sọdá Jọ́dánì, ó wá bá wọn, ó sì to àwọn jagunjagun rẹ̀ lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti dojú kọ wọ́n. Dáfídì to àwọn jagunjagun rẹ̀ lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti pàdé àwọn ará Síríà, wọ́n sì bá a jà.+ 18 Àmọ́, àwọn ará Síríà sá kúrò níwájú Ísírẹ́lì; Dáfídì pa ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) àwọn ọmọ ogun Síríà tó ń fẹsẹ̀ rìn, ó sì pa Ṣófákì olórí àwọn ọmọ ogun wọn. 19 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà rí i pé Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn,+ wọ́n tètè wá àlàáfíà lọ́dọ̀ Dáfídì, wọ́n sì di ọmọ abẹ́ rẹ̀;+ àwọn ará Síríà ò sì fẹ́ ran àwọn ọmọ Ámónì lọ́wọ́ mọ́.
20 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún,* lákòókò tí àwọn ọba máa ń jáde ogun, Jóábù+ kó àwùjọ ọmọ ogun kan jáde, ó sì run ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì; ó wá dó ti Rábà,+ àmọ́ Dáfídì dúró sí Jerúsálẹ́mù.+ Jóábù gbéjà ko Rábà, ó sì wó o palẹ̀.+ 2 Nígbà náà, Dáfídì mú adé Málíkámù kúrò ní orí rẹ̀, ó sì rí i pé ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ tálẹ́ńtì* wúrà kan àti pé àwọn òkúta iyebíye wà lára rẹ̀; a sì fi dé Dáfídì lórí. Ó tún kó ẹrù tó pọ̀ gan-an látinú ìlú náà.+ 3 Ó kó àwọn èèyàn inú rẹ̀, ó fi wọ́n sídìí iṣẹ́+ pé kí wọ́n máa fi ayùn rẹ́ òkúta, kí wọ́n sì máa fi àwọn ohun èlò onírin mímú àti àáké ṣiṣẹ́. Ohun tí Dáfídì ṣe sí gbogbo àwọn ìlú àwọn ọmọ Ámónì nìyẹn. Níkẹyìn, Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ ogun náà pa dà sí Jerúsálẹ́mù.
4 Lẹ́yìn èyí, wọ́n bá àwọn Filísínì jà ní Gésérì. Ìgbà yẹn ni Síbékáì + ọmọ Húṣà pa Sípáì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù,+ wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn Filísínì.
5 Wọ́n tún bá àwọn Filísínì jà, Élíhánánì ọmọ Jáírì pa Láámì arákùnrin Gòláyátì+ ará Gátì, ẹni tí igi ọ̀kọ̀ rẹ̀ dà bí ọ̀pá àwọn ahunṣọ.*+
6 Ogun tún wáyé ní Gátì,+ níbi tí ọkùnrin kan wà tí ó tóbi fàkìàfakia,+ ó ní ìka mẹ́fà-mẹ́fà ní ọwọ́ àti ní ẹsẹ̀, gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìnlélógún (24); òun náà sì wà lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù.+ 7 Ó ń pẹ̀gàn+ Ísírẹ́lì. Torí náà, Jónátánì ọmọ Ṣíméà,+ ẹ̀gbọ́n Dáfídì, pa á.
8 Àwọn yìí jẹ́ àtọmọdọ́mọ Réfáímù+ ní Gátì,+ Dáfídì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ló sì pa wọ́n.
21 Nígbà náà, Sátánì* dìde sí Ísírẹ́lì, ó sì mú kí Dáfídì ka iye Ísírẹ́lì.+ 2 Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Jóábù+ àti àwọn olórí àwọn èèyàn náà pé: “Lọ, ka Ísírẹ́lì láti Bíá-ṣébà dé Dánì;+ kí o sì wá jábọ̀ fún mi kí n lè mọ iye wọn.” 3 Ṣùgbọ́n Jóábù sọ pé: “Kí Jèhófà sọ àwọn èèyàn rẹ̀ di púpọ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100)! Olúwa mi ọba, ṣebí ìránṣẹ́ olúwa mi ni gbogbo wọn? Kí nìdí tí olúwa mi fi fẹ́ ṣe nǹkan yìí? Kí ló dé tí wàá fi mú kí Ísírẹ́lì jẹ̀bi?”
4 Àmọ́ ọ̀rọ̀ ọba borí ti Jóábù. Torí náà, Jóábù jáde lọ, ó sì rin gbogbo Ísírẹ́lì já, lẹ́yìn náà, ó wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 5 Jóábù wá fún Dáfídì ní iye àwọn tó forúkọ wọn sílẹ̀. Gbogbo Ísírẹ́lì jẹ́ mílíọ̀nù kan ó lé ọ̀kẹ́ márùn-ún (1,100,000) àwọn ọkùnrin tó ní idà, Júdà sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (470,000) àwọn ọkùnrin tó ní idà.+ 6 Àmọ́ Léfì àti Bẹ́ńjámínì kò sí lára àwọn tí Jóábù forúkọ wọn sílẹ̀,+ torí ohun tí ọba sọ burú lójú rẹ̀.+
7 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí burú gan-an lójú Ọlọ́run tòótọ́, torí náà, ó kọ lu Ísírẹ́lì. 8 Dáfídì wá sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀+ ńlá nítorí ohun tí mo ṣe yìí. Ní báyìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì í,+ nítorí mo ti hùwà òmùgọ̀ gan-an.”+ 9 Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá Gádì+ tó jẹ́ aríran Dáfídì sọ̀rọ̀, ó ní: 10 “Lọ sọ fún Dáfídì pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ohun mẹ́ta ni màá fi síwájú rẹ. Mú ọ̀kan tí o fẹ́ kí n ṣe sí ọ.”’” 11 Torí náà, Gádì wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Mú èyí tí o bá fẹ́, 12 bóyá kí ìyàn+ fi ọdún mẹ́ta mú tàbí kí àwọn ọ̀tá rẹ fi oṣù mẹ́ta gbá ọ dà nù bí idà àwọn ọ̀tá rẹ ti ń lé ọ bá+ tàbí kí idà Jèhófà, ìyẹn àjàkálẹ̀ àrùn ní ilẹ̀ yìí,+ fi ọjọ́ mẹ́ta jà, kí áńgẹ́lì Jèhófà sì máa pani run+ ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì.’ Ní báyìí, ro ohun tí o fẹ́ kí n sọ fún Ẹni tó rán mi.” 13 Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Gádì pé: “Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú bá mi gan-an. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Jèhófà, nítorí àánú rẹ̀ pọ̀ gidigidi;+ ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ èèyàn.”+
14 Nígbà náà, Jèhófà rán àjàkálẹ̀ àrùn+ sí Ísírẹ́lì, tó fi jẹ́ pé ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) èèyàn lára Ísírẹ́lì kú.+ 15 Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run tòótọ́ rán áńgẹ́lì kan sí Jerúsálẹ́mù láti pa á run; àmọ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà rí i, ó sì pèrò dà* lórí àjálù náà,+ ó sọ fún áńgẹ́lì tó ń pani run náà pé: “Ó tó gẹ́ẹ́!+ Gbé ọwọ́ rẹ wálẹ̀.” Áńgẹ́lì Jèhófà dúró nítòsí ibi ìpakà Ọ́nánì+ ará Jébúsì.+
16 Nígbà tí Dáfídì gbójú sókè, ó rí áńgẹ́lì Jèhófà tó dúró láàárín ayé àti ọ̀run pẹ̀lú idà tó fà yọ+ ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì nà án sí Jerúsálẹ́mù. Ní kíá, Dáfídì àti àwọn àgbààgbà tí wọ́n fi aṣọ ọ̀fọ̀*+ bora wólẹ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀.+ 17 Dáfídì sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ṣebí èmi ni mo ní kí wọ́n lọ ka àwọn èèyàn náà! Èmi ni mo ṣẹ̀, èmi ni mo sì ṣe ohun tí kò dáa;+ àmọ́ kí ni àwọn àgùntàn yìí ṣe? Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, jọ̀ọ́, èmi àti ilé bàbá mi ni kí o gbé ọwọ́ rẹ sókè sí; má ṣe mú àjàkálẹ̀ àrùn yìí wá sórí àwọn èèyàn rẹ.”+
18 Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì Jèhófà ní kí Gádì+ sọ fún Dáfídì pé kó lọ ṣé pẹpẹ kan fún Jèhófà ní ibi ìpakà Ọ́nánì ará Jébúsì.+ 19 Torí náà, Dáfídì lọ ṣe ohun tí Gádì sọ, èyí tó sọ fún un ní orúkọ Jèhófà. 20 Lákòókò yìí, Ọ́nánì bojú wẹ̀yìn, ó rí áńgẹ́lì náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì fara pa mọ́. Nígbà yẹn, Ọ́nánì ń pa ọkà àlìkámà.* 21 Nígbà tí Dáfídì dé ọ̀dọ̀ Ọ́nánì, Ọ́nánì gbójú sókè, ó sì rí Dáfídì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kúrò ní ibi ìpakà náà, ó tẹrí ba fún Dáfídì, ó sì dojú bolẹ̀. 22 Dáfídì sọ fún Ọ́nánì pé: “Ta* ilẹ̀ tó wá ní ibi ìpakà yìí fún mi, kí n lè mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà. Iye tó bá jẹ́ ni kí o tà á fún mi, kí àjàkálẹ̀ àrùn tó ń pa àwọn èèyàn yìí lè dáwọ́ dúró.”+ 23 Ṣùgbọ́n Ọ́nánì sọ fún Dáfídì pé: “Máa mú un, kí olúwa mi ọba ṣe ohun tó bá rí pé ó dára.* Mo tún fi màlúù sílẹ̀ fún àwọn ẹbọ sísun àti ohun èlò ìpakà+ láti fi ṣe igi ìdáná àti àlìkámà* fún ọrẹ ọkà. Gbogbo rẹ̀ ni mo fi sílẹ̀.”
24 Àmọ́, Ọba Dáfídì sọ fún Ọ́nánì pé: “Rárá o, iye tó bá jẹ́ ni màá rà á, torí mi ò ní gba ohun tó jẹ́ tìrẹ kì n sì fún Jèhófà tàbí kí n fi rú àwọn ẹbọ sísun láìná nǹkan kan.”+ 25 Nítorí náà, Dáfídì fún Ọ́nánì ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ṣékélì* wúrà fún ilẹ̀ náà. 26 Dáfídì mọ pẹpẹ kan+ síbẹ̀ fún Jèhófà, ó sì rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ó ké pe Jèhófà, ẹni tó wá fi iná dá a lóhùn+ láti ọ̀run sórí pẹpẹ ẹbọ sísun náà. 27 Lẹ́yìn náà, Jèhófà pàṣẹ fún áńgẹ́lì+ náà pé kí ó dá idà rẹ̀ pa dà sínú àkọ̀ rẹ̀. 28 Lákòókò yẹn, nígbà tí Dáfídì rí i pé Jèhófà ti dá òun lóhùn ní ibi ìpakà Ọ́nánì ará Jébúsì, ó ń rúbọ níbẹ̀ nìṣó. 29 Àgọ́ ìjọsìn Jèhófà tí Mósè ṣe ní aginjù àti pẹpẹ ẹbọ sísun ṣì wà ní ibi gíga Gíbíónì+ ní àkókò yẹn. 30 Àmọ́ Dáfídì kò tíì lọ síwájú rẹ̀ láti wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run, nítorí ẹ̀rù idà áńgẹ́lì Jèhófà ń bà á.
22 Nígbà náà, Dáfídì sọ pé: “Ilé Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ nìyí, pẹpẹ ẹbọ sísun fún Ísírẹ́lì sì nìyí.”+
2 Dáfídì wá pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn àjèjì+ tó wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì jọ, ó sì yàn wọ́n ṣe agbẹ́kùúta láti máa gé òkúta, kí wọ́n sì máa gbẹ́ òkúta tí wọ́n á fi kọ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́.+ 3 Dáfídì tún pèsè irin tó pọ̀ gan-an láti fi ṣe ìṣó ilẹ̀kùn àwọn ẹnubodè àti àwọn ẹ̀mú,* bákan náà, ó pèsè bàbà tó pọ̀ débi pé kò ṣeé wọ̀n+ 4 àti ẹ̀là gẹdú kédárì+ tí kò níye, nítorí àwọn ọmọ Sídónì + àti àwọn ará Tírè+ kó ẹ̀là gẹdú kédárì tó pọ̀ gan-an wá fún Dáfídì. 5 Dáfídì sì sọ pé: “Sólómọ́nì ọmọ mi jẹ́ ọ̀dọ́, kò sì ní ìrírí,*+ ilé tí a máa kọ́ fún Jèhófà sì máa lẹ́wà yàtọ̀,+ kí wọ́n lè gbọ́ nípa òkìkí àti ẹwà rẹ̀+ ní gbogbo ilẹ̀.+ Nítorí náà, màá pèsè àwọn nǹkan sílẹ̀ fún un.” Dáfídì wá pèsè ọ̀pọ̀ nǹkan ìkọ́lé sílẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀.
6 Ó tún pe Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀, ó sì ní kó kọ́ ilé fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 7 Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Ní tèmi, ìfẹ́ ọkàn mi ni láti kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi.+ 8 Àmọ́ Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, ‘O ti ta ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ gan-an sílẹ̀, o sì ti ja àwọn ogun ńlá. O ò ní kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ nítorí o ti ta ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ gan-an sílẹ̀ níwájú mi. 9 Wò ó! Wàá bí ọmọkùnrin kan+ tó máa jẹ́ ẹni àlàáfíà,* màá sì fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó yí i ká,+ Sólómọ́nì*+ ni orúkọ tí a máa pè é, màá sì fi àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ jíǹkí Ísírẹ́lì ní ìgbà ayé rẹ̀.+ 10 Òun ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.+ Á di ọmọ mi, màá sì di bàbá rẹ̀.+ Màá fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì títí láé.’+
11 “Wò ó, ọmọ mi, kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, kí o ṣe àṣeyọrí, kí o sì kọ́ ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.+ 12 Kìkì pé kí Jèhófà fún ọ ní làákàyè àti òye+ nígbà tó bá fún ọ ní àṣẹ lórí Ísírẹ́lì, kí o lè máa pa òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́.+ 13 Wàá sì ṣàṣeyọrí tí o bá rí i pé o tẹ̀ lé àwọn ìlànà+ àti ìdájọ́ tí Jèhófà ní kí Mósè fún Ísírẹ́lì.+ Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má bẹ̀rù, má sì jáyà.+ 14 Wò ó, mo ti sapá gan-an láti pèsè ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) tálẹ́ńtì* wúrà sílẹ̀ fún ilé Jèhófà àti mílíọ̀nù kan (1,000,000) tálẹ́ńtì fàdákà pẹ̀lú bàbà àti irin+ tó pọ̀ gan-an débi pé kò ṣeé wọ̀n, mo sì ti pèsè àwọn ẹ̀là gẹdú àti òkúta+ sílẹ̀, àmọ́ wàá fi kún wọn. 15 Àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ wà pẹ̀lú rẹ, ìyẹn àwọn agbẹ́kùúta, àwọn oníṣẹ́ òkúta+ àti àwọn oníṣẹ́ igi pẹ̀lú onírúurú àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́.+ 16 Wúrà, fàdákà, bàbà àti irin náà pọ̀ débi pé kò ṣeé wọ̀n.+ Dìde kí o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà, kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.”+
17 Dáfídì wá pàṣẹ fún gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ran Sólómọ́nì ọmọ òun lọ́wọ́, ó ní: 18 “Ṣebí Jèhófà Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú yín, ṣebí ó ti fún yín ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá tó yí yín ká? Nítorí ó fi àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́, a sì ti ṣẹ́gun ilẹ̀ náà níwájú Jèhófà àti àwọn èèyàn rẹ̀. 19 Ní báyìí, ẹ pinnu pé ẹ máa fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín wá Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ibi mímọ́ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́,+ láti gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà àti àwọn nǹkan èlò mímọ́ ti Ọlọ́run tòótọ́+ wá sínú ilé tí a kọ́ fún orúkọ Jèhófà.”+
23 Nígbà tí Dáfídì darúgbó, tí kò sì ní pẹ́ kú mọ́,* ó fi Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ jọba lórí Ísírẹ́lì.+ 2 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì jọ àti àwọn àlùfáà + pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì.+ 3 Wọ́n ka iye+ àwọn ọmọ Léfì láti ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sókè; iye àwọn ọkùnrin tí wọ́n kà lọ́kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìdínlógójì (38,000). 4 Ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) lára wọn ń ṣe alábòójútó lórí iṣẹ́ ilé Jèhófà, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) sì jẹ́ aláṣẹ àti onídàájọ́,+ 5 ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) jẹ́ aṣọ́bodè,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) sì ń fi àwọn ohun ìkọrin yin+ Jèhófà, èyí tí Dáfídì sọ nípa wọn pé “mo ṣe wọ́n fún kíkọ orin ìyìn.”
6 Lẹ́yìn náà, Dáfídì ṣètò* wọn sí àwùjọ-àwùjọ+ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Léfì ṣe wà: Gẹ́ṣónì, Kóhátì àti Mérárì.+ 7 Lára àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì ni Ládánì àti Ṣíméì. 8 Àwọn ọmọ Ládánì ni Jéhíélì tó jẹ́ olórí, Sétámù àti Jóẹ́lì,+ wọ́n jẹ́ mẹ́ta. 9 Àwọn ọmọ Ṣíméì ni Ṣẹ́lómótì, Hásíélì àti Háránì, wọ́n jẹ́ mẹ́ta. Àwọn ni olórí àwọn agbo ilé Ládánì. 10 Àwọn ọmọ Ṣíméì ni Jáhátì, Sínà, Jéúṣì àti Bẹráyà. Àwọn mẹ́rin yìí ni ọmọ Ṣíméì. 11 Jáhátì ni olórí, Sísáhì sì ni ìkejì. Ṣùgbọ́n torí pé àwọn ọmọ Jéúṣì àti ti Bẹráyà kò pọ̀, agbo ilé kan ṣoṣo ni wọ́n kà wọ́n sí, wọ́n sì yan iṣẹ́ kan fún wọn láti máa bójú tó.
12 Àwọn ọmọ Kóhátì ni Ámúrámù, Ísárì,+ Hébúrónì àti Úsíélì,+ wọ́n jẹ́ mẹ́rin. 13 Àwọn ọmọ Ámúrámù ni Áárónì+ àti Mósè.+ Àmọ́ a ya Áárónì sọ́tọ̀+ láti máa sìn ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ títí lọ, kí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ máa rú ẹbọ níwájú Jèhófà, kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́ fún un, kí wọ́n sì máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún àwọn èèyàn nígbà gbogbo.+ 14 Ní ti Mósè èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ka àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́ ẹ̀yà àwọn ọmọ Léfì. 15 Àwọn ọmọ Mósè ni Gẹ́ṣómù+ àti Élíésérì.+ 16 Nínú àwọn ọmọ Gẹ́ṣómù, Ṣẹ́búẹ́lì+ ni olórí. 17 Nínú àtọmọdọ́mọ* Élíésérì, Rehabáyà+ ni olórí; Élíésérì kò ní ọmọkùnrin míì, àmọ́ àwọn ọmọkùnrin Rehabáyà pọ̀ gan-an. 18 Nínú àwọn ọmọ Ísárì,+ Ṣẹ́lómítì+ ni olórí. 19 Àwọn ọmọ Hébúrónì ni Jeráyà tó jẹ́ olórí, Amaráyà ìkejì, Jáhásíẹ́lì ìkẹta àti Jekaméámì+ ìkẹrin. 20 Àwọn ọmọ Úsíélì+ ni Míkà tó jẹ́ olórí àti Isiṣáyà ìkejì.
21 Àwọn ọmọ Mérárì ni Máhílì àti Múṣì.+ Àwọn ọmọ Máhílì ni Élíásárì àti Kíṣì. 22 Élíásárì kú, kò ní ọmọkùnrin, àmọ́ ó ní àwọn ọmọbìnrin. Torí náà, àwọn ọmọ Kíṣì tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí* wọn fi wọ́n ṣe aya. 23 Àwọn ọmọ Múṣì ni Máhílì, Édérì àti Jérémótì, wọ́n jẹ́ mẹ́ta.
24 Àwọn yìí ni àwọn ọmọ Léfì, bí wọ́n ṣe wà nínú agbo ilé bàbá wọn, àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn, àwọn tí wọ́n kà, tí orúkọ wọn sì wà lákọsílẹ̀, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ìsìn ní ilé Jèhófà, láti ẹni ogún (20) ọdún sókè. 25 Nítorí Dáfídì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìsinmi,+ yóò sì máa gbé ní Jerúsálẹ́mù títí láé.+ 26 Bákan náà, àwọn ọmọ Léfì kò ní máa ru àgọ́ ìjọsìn tàbí èyíkéyìí lára àwọn nǹkan èlò rẹ̀ tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn.”+ 27 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Dáfídì sọ kẹ́yìn pé kí wọ́n ṣe, wọ́n ka iye àwọn ọmọ Léfì láti ẹni ogún (20) ọdún sókè. 28 Iṣẹ́ wọn ni láti máa ran àwọn ọmọ Áárónì+ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà, kí wọ́n máa bójú tó àwọn àgbàlá,+ àwọn yàrá ìjẹun, mímú kí gbogbo ohun mímọ́ wà ní mímọ́ àti iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yọjú nínú iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́. 29 Wọ́n ń ṣe búrẹ́dì onípele*+ àti ìyẹ̀fun kíkúnná tí wọ́n ń lò fún ọrẹ ọkà, wọ́n tún ń ṣe àwọn búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ+ àti àwọn àkàrà tí wọ́n fi agbada dín, wọ́n ń po ìyẹ̀fun títí á fi rọ́,+ wọ́n sì ń díwọ̀n bí nǹkan ṣe pọ̀ tó àti bí ó ṣe tóbi tó. 30 Iṣẹ́ wọn ni láti máa dúró ní àràárọ̀ + láti máa dúpẹ́, kí wọ́n sì máa yin Jèhófà, ohun kan náà ni wọ́n sì ń ṣe ní ìrọ̀lẹ́.+ 31 Wọ́n ń ṣèrànwọ́ nígbàkigbà tí wọ́n bá ń rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà ní àwọn Sábáàtì,+ ní àwọn òṣùpá tuntun+ àti ní àwọn àsìkò àjọyọ̀,+ gẹ́gẹ́ bí iye àwọn tí òfin sọ nípa àwọn nǹkan yìí, wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo níwájú Jèhófà. 32 Wọ́n tún ń ṣe ojúṣe wọn ní àgọ́ ìpàdé àti ní ibi mímọ́. Wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọmọ Áárónì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà.
24 Bí a ṣe pín àtọmọdọ́mọ àwọn ọmọ Áárónì nìyí: Àwọn ọmọ Áárónì ni Nádábù, Ábíhù,+ Élíásárì àti Ítámárì.+ 2 Nádábù àti Ábíhù kú ṣáájú bàbá wọn,+ wọn ò sì ní ọmọkùnrin kankan; àmọ́ Élíásárì+ àti Ítámárì ń ṣiṣẹ́ àlùfáà nìṣó. 3 Dáfídì àti Sádókù+ látinú àwọn ọmọ Élíásárì àti Áhímélékì látinú àwọn ọmọ Ítámárì pín wọn sí àwùjọ-àwùjọ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn. 4 Torí pé olórí tí àwọn ọmọ Élíásárì ní pọ̀ ju ti àwọn ọmọ Ítámárì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe pín wọn: Àwọn ọmọ Élíásárì ní àwọn mẹ́rìndínlógún (16) tó jẹ́ olórí àwọn agbo ilé bàbá wọn, àwọn ọmọ Ítámárì sì ní àwọn mẹ́jọ tó jẹ́ olórí àwọn agbo ilé bàbá wọn.
5 Síwájú sí i, wọ́n fi kèké pín wọn,+ àwùjọ kan pẹ̀lú àwùjọ kejì, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ti Ọlọ́run tòótọ́ wá látinú àwọn ọmọ Élíásárì àti àwọn ọmọ Ítámárì. 6 Lẹ́yìn náà, Ṣemáyà ọmọ Nétánélì akọ̀wé àwọn ọmọ Léfì kọ orúkọ wọn sílẹ̀ níwájú ọba àti àwọn ìjòyè àti àlùfáà Sádókù+ àti Áhímélékì+ ọmọ Ábíátárì+ àti àwọn olórí àwọn agbo ilé bàbá àwọn àlùfáà àti ti àwọn ọmọ Léfì, agbo ilé kan ni wọ́n yàn fún Élíásárì, agbo ilé kan ni wọ́n sì yàn fún Ítámárì.
7 Kèké àkọ́kọ́ jáde fún Jèhóáríbù; ìkejì fún Jedáyà, 8 ìkẹta fún Hárímù, ìkẹrin fún Séórímù, 9 ìkarùn-ún fún Málíkíjà, ìkẹfà fún Míjámínì, 10 ìkeje fún Hákósì, ìkẹjọ fún Ábíjà,+ 11 ìkẹsàn-án fún Jéṣúà, ìkẹwàá fún Ṣẹkanáyà, 12 ìkọkànlá fún Élíáṣíbù, ìkejìlá fún Jákímù, 13 ìkẹtàlá fún Húpà, ìkẹrìnlá fún Jéṣébéábù, 14 ìkẹẹ̀ẹ́dógún fún Bílígà, ìkẹrìndínlógún fún Ímérì, 15 ìkẹtàdínlógún fún Hésírì, ìkejìdínlógún fún Hápísésì, 16 ìkọkàndínlógún fún Petaháyà, ogún fún Jéhésíkélì, 17 ìkọkànlélógún fún Jákínì, ìkejìlélógún fún Gámúlì, 18 ìkẹtàlélógún fún Deláyà, ìkẹrìnlélógún fún Maasáyà.
19 Bí a ṣe ṣètò iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn+ nígbà tí wọ́n bá wá sínú ilé Jèhófà nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí Áárónì baba ńlá wọn ṣe là á kalẹ̀ àti bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣe pa á láṣẹ fún un.
20 Àwọn ọmọ Léfì tó ṣẹ́ kù nìyí: Ṣúbáélì+ látinú àwọn ọmọ Ámúrámù;+ Jedeáyà látinú àwọn ọmọ Ṣúbáélì; 21 lára Rehabáyà:+ Isiṣáyà tó jẹ́ olórí látinú àwọn ọmọ Rehabáyà; 22 Ṣẹ́lómótì+ látinú àwọn ọmọ Ísárì; Jáhátì látinú àwọn ọmọ Ṣẹ́lómótì; 23 àti látinú àwọn ọmọ Hébúrónì, Jeráyà+ ni olórí, Amaráyà ìkejì, Jáhásíẹ́lì ìkẹta, Jekaméámì ìkẹrin; 24 Míkà látinú àwọn ọmọ Úsíélì; Ṣámírù látinú àwọn ọmọ Míkà. 25 Arákùnrin Míkà ni Isiṣáyà; Sekaráyà sì wá látinú àwọn ọmọ Isiṣáyà.
26 Àwọn ọmọ Mérárì+ ni Máhílì àti Múṣì; Bénò látinú àwọn ọmọ Jaasáyà. 27 Àwọn ọmọ Mérárì nìyí: látọ́dọ̀ Jaasáyà, Bénò, Ṣóhámù, Sákúrì àti Íbírì; 28 látọ̀dọ̀ Máhílì, Élíásárì tí kò ní ọmọkùnrin kankan;+ 29 látọ̀dọ̀ Kíṣì: àwọn ọmọ Kíṣì ni Jéráméélì; 30 àwọn ọmọ Múṣì sì ni Máhílì, Édérì àti Jérímótì.
Àwọn ni àwọn ọmọ Léfì bí wọ́n ṣe wà nínú àwọn agbo ilé bàbá wọn. 31 Àwọn náà tún ṣẹ́ kèké+ bí àwọn ọmọ Áárónì tó jẹ́ arákùnrin wọn ti ṣe níwájú Ọba Dáfídì àti Sádókù àti Áhímélékì àti àwọn olórí àwọn agbo ilé bàbá àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì. Ní ti àwọn agbo ilé bàbá, bí olórí ṣe jẹ́ náà ni àbúrò rẹ̀ ọkùnrin ṣe jẹ́.
25 Síwájú sí i, Dáfídì àti àwọn olórí àwùjọ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn ya àwọn kan lára àwọn ọmọ Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì+ sọ́tọ̀ láti máa fi háàpù, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti síńbálì*+ sọ tẹ́lẹ̀. Orúkọ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn yìí ni, 2 látinú àwọn ọmọ Ásáfù: Sákúrì, Jósẹ́fù, Netanáyà àti Áṣárélà, àwọn ọmọ Ásáfù lábẹ́ ìdarí Ásáfù, ẹni tó ń sọ tẹ́lẹ̀ lábẹ́ àṣẹ ọba. 3 Látinú Jédútúnì,+ àwọn ọmọ Jédútúnì ni: Gẹdaláyà, Séérì, Jeṣáyà, Ṣíméì, Haṣabáyà àti Matitáyà,+ wọ́n jẹ́ mẹ́fà lábẹ́ ìdarí bàbá wọn Jédútúnì, ẹni tó ń fi háàpù sọ tẹ́lẹ̀, láti máa dúpẹ́ àti láti máa yin Jèhófà.+ 4 Látinú Hémánì,+ àwọn ọmọ Hémánì ni: Bùkáyà, Matanáyà, Úsíélì, Ṣẹ́búẹ́lì, Jérímótì, Hananáyà, Hánáánì, Élíátà, Gídálítì, Romamuti-ésérì, Joṣibẹ́káṣà, Málótì, Hótírì àti Máhásíótì. 5 Gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Hémánì, aríran ọba tó bá ti kan ohun tó jẹ mọ́ Ọlọ́run tòótọ́ láti gbé e* ga; torí náà, Ọlọ́run tòótọ́ fún Hémánì ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá (14) àti ọmọbìnrin mẹ́ta. 6 Gbogbo wọn wà lábẹ́ ìdarí bàbá wọn láti máa kọrin ní ilé Jèhófà pẹ̀lú síńbálì, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́.
Àwọn tó wà lábẹ́ àṣẹ ọba ni Ásáfù, Jédútúnì àti Hémánì.
7 Àwọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn tí a ti kọ́ níṣẹ́ orin láti máa kọrin sí Jèhófà jẹ́ igba ó lé ọgọ́rin àti mẹ́jọ (288), gbogbo wọn jẹ́ ọ̀jáfáfá. 8 Torí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké+ lórí iṣẹ́ wọn, bí ti ẹni kékeré ṣe rí bẹ́ẹ̀ ni ti ẹni ńlá, bíi ti ọ̀jáfáfá náà sì ni ti akẹ́kọ̀ọ́.
9 Kèké tó kọ́kọ́ jáde jẹ́ ti Ásáfù fún Jósẹ́fù,+ ìkejì fún Gẹdaláyà+ (òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ méjìlá [12]); 10 ìkẹta fún Sákúrì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 11 ìkẹrin fún Ísíráì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 12 ìkarùn-ún fún Netanáyà,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 13 ìkẹfà fún Bùkáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 14 ìkeje fún Jéṣárélà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 15 ìkẹjọ fún Jeṣáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 16 ìkẹsàn-án fún Matanáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 17 ìkẹwàá fún Ṣíméì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 18 ìkọkànlá fún Ásárẹ́lì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 19 ìkejìlá fún Haṣabáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 20 ìkẹtàlá fún Ṣúbáélì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 21 ìkẹrìnlá fún Matitáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 22 ìkẹẹ̀ẹ́dógún fún Jérémótì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 23 ìkẹrìndínlógún fún Hananáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 24 ìkẹtàdínlógún fún Joṣibẹ́káṣà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 25 ìkejìdínlógún fún Hánáánì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 26 ìkọkàndínlógún fún Málótì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 27 ogún fún Élíátà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 28 ìkọkànlélógún fún Hótírì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 29 ìkejìlélógún fún Gídálítì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 30 ìkẹtàlélógún fún Máhásíótì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 31 ìkẹrìnlélógún fún Romamuti-ésérì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12).
26 Bí wọ́n ṣe pín àwọn aṣọ́bodè+ nìyí: nínú àwọn ọmọ Kórà, Meṣelemáyà+ ọmọ Kórè látinú àwọn ọmọ Ásáfù. 2 Meṣelemáyà ní àwọn ọmọkùnrin: Sekaráyà ni àkọ́bí, Jédáélì ìkejì, Sebadáyà ìkẹta, Játíníélì ìkẹrin, 3 Élámù ìkarùn-ún, Jèhóhánánì ìkẹfà, Elieho-énáì ìkeje. 4 Obedi-édómù ní àwọn ọmọkùnrin: Ṣemáyà ni àkọ́bí, Jèhósábádì ìkejì, Jóà ìkẹta, Sákà ìkẹrin, Nétánélì ìkarùn-ún, 5 Ámíélì ìkẹfà, Ísákà ìkeje àti Péúlétáì ìkẹjọ; nítorí pé Ọlọ́run bù kún un.
6 Wọ́n bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣemáyà ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ náà di olórí agbo ilé bàbá wọn nítorí wọ́n jẹ́ akíkanjú àti ọ̀jáfáfá ọkùnrin. 7 Àwọn ọmọkùnrin Ṣemáyà ni: Ótínì, Réfáélì, Óbédì àti Élísábádì; àwọn arákùnrin rẹ̀ Élíhù àti Semakáyà náà jẹ́ ọ̀jáfáfá. 8 Gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Obedi-édómù; àwọn àti àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn jẹ́ ọ̀jáfáfá, wọ́n sì kúnjú ìwọ̀n fún iṣẹ́ ìsìn náà, méjìlélọ́gọ́ta (62) jẹ́ ti Obedi-édómù. 9 Meṣelemáyà+ ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn arákùnrin, àwọn méjìdínlógún (18) tó jẹ́ ọ̀jáfáfá. 10 Hósà látinú àwọn ọmọ Mérárì ní àwọn ọmọkùnrin. Ṣímúrì ni olórí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun kọ́ ni àkọ́bí, bàbá rẹ̀ yàn án ṣe olórí, 11 Hilikáyà ìkejì, Tebaláyà ìkẹta, Sekaráyà ìkẹrin. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti àwọn arákùnrin Hósà jẹ́ mẹ́tàlá (13).
12 Nínú àwọn àwùjọ tí a pín àwọn aṣọ́bodè yìí sí, bí àwọn olórí ṣe ní iṣẹ́ ni àwọn arákùnrin wọn náà ṣe ní iṣẹ́, láti máa ṣe ìránṣẹ́ ní ilé Jèhófà. 13 Torí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké+ fún ẹni kékeré bí wọ́n ṣe ṣẹ́ ẹ fún ẹni ńlá ní agbo ilé bàbá wọn, fún ẹnubodè kọ̀ọ̀kan. 14 Nígbà náà, kèké tí wọ́n ṣẹ́ fún ẹnubodè ìlà oòrùn jáde fún Ṣelemáyà. Wọ́n ṣẹ́ kèké náà fún Sekaráyà ọmọ rẹ̀, agbani-nímọ̀ràn tó lóye, kèké rẹ̀ sì mú àríwá. 15 Kèké Obedi-édómù mú gúúsù, a sì yan àwọn ilé ìkẹ́rùsí fún àwọn ọmọ rẹ̀.+ 16 Kèké Ṣúpímù àti Hósà+ mú ìwọ̀ oòrùn nítòsí Ẹnubodè Ṣálékétì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà tó lọ sókè, àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́ kan sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́ míì; 17 àwọn ọmọ Léfì mẹ́fà ló wà lápá ìlà oòrùn; mẹ́rin lápá àríwá fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àti mẹ́rin lápá gúúsù fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan; àwọn méjì-méjì sì wà ní àwọn ilé ìkẹ́rùsí;+ 18 fún ọ̀nà olórùlé tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹ́rin wà ní ojú ọ̀nà,+ àwọn méjì sì wà ní ọ̀nà olórùlé náà. 19 Bí wọ́n ṣe pín àwọn aṣọ́bodè náà nìyẹn látinú àwọn ọmọ Kórà àti àwọn ọmọ Mérárì.
20 Ní ti àwọn ọmọ Léfì, Áhíjà ló ń bójú tó àwọn ibi ìṣúra ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti àwọn ibi ìṣúra tí wọ́n ń kó àwọn ohun tí a sọ di* mímọ́+ sí. 21 Àwọn ọmọ Ládánì nìyí: àwọn ọmọkùnrin látinú àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì tí Ládánì bí, àwọn olórí agbo ilé Ládánì ọmọ Gẹ́ṣónì, Jẹ́híélì+ 22 àti àwọn ọmọ Jẹ́híélì, Sétámù àti Jóẹ́lì arákùnrin rẹ̀. Àwọn ló ń bójú tó àwọn ibi ìṣúra ilé Jèhófà.+ 23 Látinú àwọn ọmọ Ámúrámù, àwọn ọmọ Ísárì, àwọn ọmọ Hébúrónì àti àwọn ọmọ Úsíélì,+ 24 Ṣẹ́búẹ́lì ọmọ Gẹ́ṣómù ọmọ Mósè jẹ́ aṣáájú tó ń bójú tó àwọn ilé ìkẹ́rùsí. 25 Àwọn arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Élíésérì+ ni Rehabáyà,+ Jeṣáyà, Jórámù, Síkírì àti Ṣẹ́lómótì. 26 Ṣẹ́lómótì yìí àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ló ń bójú tó gbogbo àwọn ibi ìṣúra tí wọ́n ń kó àwọn ohun tí a sọ di mímọ́+ sí, tí Ọba Dáfídì+ àti àwọn olórí agbo ilé+ àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún pẹ̀lú àwọn olórí ọmọ ogun ti sọ di mímọ́. 27 Lára àwọn ẹrù + tí wọ́n kó lójú ogun,+ wọ́n ya àwọn ohun kan sí mímọ́ láti máa fi tọ́jú ilé Jèhófà; 28 bákan náà ni gbogbo ohun tí Sámúẹ́lì aríran,+ Sọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, Ábínérì+ ọmọ Nérì àti Jóábù+ ọmọ Seruáyà+ sọ di mímọ́. Ohun tí ẹnikẹ́ni bá sọ di mímọ́ ni wọ́n ń fi sí abẹ́ àbójútó Ṣẹ́lómítì àti àwọn arákùnrin rẹ̀.
29 Nínú àwọn ọmọ Ísárì,+ wọ́n fún Kenanáyà àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní iṣẹ́ àmójútó ní ìta láti jẹ́ aláṣẹ àti onídàájọ́+ lórí Ísírẹ́lì.
30 Nínú àwọn ọmọ Hébúrónì,+ Haṣabáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje (1,700) ọkùnrin tó jẹ́ ọ̀jáfáfá, ni wọ́n ń bójú tó Ísírẹ́lì ní ìwọ̀ oòrùn agbègbè Jọ́dánì láti máa ṣe gbogbo iṣẹ́ Jèhófà àti iṣẹ́ ọba. 31 Nínú àwọn ọmọ Hébúrónì, Jéríjà+ ni olórí àwọn ọmọ Hébúrónì bí ìran wọn ṣe tẹ̀ léra nínú agbo ilé bàbá wọn. Ní ogójì ọdún ìjọba Dáfídì,+ wọ́n wá àwọn akíkanjú àti ọ̀jáfáfá ọkùnrin, wọ́n sì rí láàárín àwọn ọmọ Hébúrónì ní Jásérì+ ní Gílíádì. 32 Àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀jáfáfá àti olórí nínú àwọn agbo ilé bàbá wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-un méje (2,700). Torí náà, Ọba Dáfídì fi wọ́n ṣe olórí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè, láti máa bójú tó gbogbo ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ti Ọlọ́run tòótọ́ àti ti ọba.
27 Iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, àwọn olórí nínú àwọn agbo ilé, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ àti àwọn aláṣẹ wọn tó ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba+ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ àwọn àwùjọ tó ń wọlé àti àwọn tó ń jáde ní oṣooṣù ní gbogbo oṣù tó wà nínú ọdún; ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ kọ̀ọ̀kan.
2 Jáṣóbéámù+ ọmọ Sábídíẹ́lì ni olórí àwùjọ kìíní ti oṣù kìíní, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 3 Nínú àwọn ọmọ Pérésì,+ òun ni aṣáájú gbogbo olórí àwọn àwùjọ tí wọ́n yàn láti ṣiṣẹ́ ní oṣù kìíní. 4 Dódáì+ ọmọ Áhóhì + ni olórí àwùjọ tó wà fún oṣù kejì, Míkílótì ni aṣáájú, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 5 Olórí àwùjọ kẹta tí wọ́n yàn láti ṣiṣẹ́ ní oṣù kẹta ni Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà+ olórí àlùfáà, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 6 Bẹnáyà yìí jẹ́ jagunjagun tó lákíkanjú lára àwọn ọgbọ̀n (30) náà, òun ló ń bójú tó àwọn ọgbọ̀n (30) náà, Ámísábádì ọmọ rẹ̀ ló sì ń bójú tó àwùjọ rẹ̀. 7 Olórí àwùjọ kẹrin fún oṣù kẹrin ni Ásáhélì,+ arákùnrin Jóábù,+ Sebadáyà ọmọ rẹ̀ ló tẹ̀ lé e, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 8 Olórí àwùjọ karùn-ún fún oṣù karùn-ún ni Ṣámíhútì tó jẹ́ Ísíráhì, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 9 Olórí àwùjọ kẹfà fún oṣù kẹfà ni Írà+ ọmọ Íkéṣì ará Tékóà,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 10 Olórí àwùjọ keje fún oṣù keje ni Hélésì+ tó jẹ́ Pélónì látinú àwọn ọmọ Éfúrémù, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 11 Olórí àwùjọ kẹjọ fún oṣù kẹjọ ni Síbékáì+ ọmọ Húṣà látinú àwọn ọmọ Síírà,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 12 Olórí àwùjọ kẹsàn-án fún oṣù kẹsàn-án ni Abi-ésérì + ọmọ Ánátótì+ látinú àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 13 Olórí àwùjọ kẹwàá fún oṣù kẹwàá ni Máháráì+ ará Nétófà látinú àwọn ọmọ Síírà,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 14 Olórí àwùjọ kọkànlá fún oṣù kọkànlá ni Bẹnáyà+ ará Pírátónì látinú àwọn ọmọ Éfúrémù, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 15 Olórí àwùjọ kejìlá fún oṣù kejìlá ni Hélídáì ará Nétófà, láti ìdílé Ótíníẹ́lì, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀.
16 Àwọn aṣáájú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì nìyí: Nínú àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, Élíésérì ọmọ Síkírì ni aṣáájú; nínú àwọn ọmọ Síméónì, Ṣẹfatáyà ọmọ Máákà; 17 nínú ẹ̀yà Léfì, Haṣabáyà ọmọ Kémúélì; nínú àwọn ọmọ Áárónì, Sádókù; 18 nínú ẹ̀yà Júdà, Élíhù+ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin Dáfídì; nínú ẹ̀yà Ísákà, Ómírì ọmọ Máíkẹ́lì; 19 nínú ẹ̀yà Sébúlúnì, Iṣimáyà ọmọ Ọbadáyà; nínú ẹ̀yà Náfútálì, Jérímótì ọmọ Ásíríẹ́lì; 20 nínú àwọn ọmọ Éfúrémù, Hóṣéà ọmọ Asasáyà; nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, Jóẹ́lì ọmọ Pedáyà; 21 nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní Gílíádì, Ídò ọmọ Sekaráyà; nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Jáásíélì ọmọ Ábínérì;+ 22 nínú ẹ̀yà Dánì, Ásárẹ́lì ọmọ Jéróhámù. Àwọn ni ìjòyè àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
23 Dáfídì kò ka àwọn tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sísàlẹ̀, nítorí pé Jèhófà ti ṣèlérí láti sọ Ísírẹ́lì di púpọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.+ 24 Jóábù ọmọ Seruáyà bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn èèyàn, àmọ́ kò kà wọ́n parí; Ọlọ́run bínú sí Ísírẹ́lì* nítorí nǹkan yìí,+ a kò sì kọ iye náà sínú àkọsílẹ̀ ìtàn ìgbà Ọba Dáfídì.
25 Ásímáfẹ́tì ọmọ Ádíélì ló ń bójú tó àwọn ibi ìṣúra ọba.+ Jónátánì ọmọ Ùsáyà ló ń bójú tó àwọn ilé ìkẹ́rùsí* ní pápá, ní àwọn ìlú, ní àwọn abúlé àti ní àwọn ilé gogoro. 26 Ẹ́síráì ọmọ Kélúbù ló ń bójú tó àwọn òṣìṣẹ́ inú pápá tó ń dáko. 27 Ṣíméì ará Rámà ló ń bójú tó àwọn ọgbà àjàrà; Sábídì tó jẹ́ Ṣífímì ló ń bójú tó àwọn ohun tó wá látinú àwọn ọgbà àjàrà fún ṣíṣe wáìnì. 28 Baali-hánánì ará Gédérì ló ń bójú tó àwọn oko ólífì àti àwọn igi síkámórè+ tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là;+ Jóáṣì ló sì ń bójú tó òróró. 29 Ṣítíráì ará Ṣárónì ló ń bójú tó àwọn ọ̀wọ́ ẹran tó ń jẹko ní Ṣárónì,+ Ṣáfátì ọmọ Ádíláì ló sì ń bójú tó àwọn ọ̀wọ́ ẹran tó wà ní àwọn àfonífojì.* 30 Óbílì ọmọ Íṣímáẹ́lì ló ń bójú tó àwọn ràkúnmí; Jedeáyà ará Mérónótì ló ń bójú tó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.* 31 Jásísì ọmọ Hágárì ló ń bójú tó àwọn agbo ẹran. Gbogbo wọn ni olórí tó ń bójú tó àwọn ohun ìní Ọba Dáfídì.
32 Jónátánì,+ ọmọ arákùnrin Dáfídì, jẹ́ agbani-nímọ̀ràn, ọkùnrin olóye ni, ó tún jẹ́ akọ̀wé, Jéhíélì ọmọ Hákímónì sì ń bójú tó àwọn ọmọ ọba.+ 33 Áhítófẹ́lì+ jẹ́ agbani-nímọ̀ràn ọba, Húṣáì+ tó jẹ́ Áríkì sì ni ọ̀rẹ́* ọba. 34 Lẹ́yìn Áhítófẹ́lì, ó kan Jèhóádà ọmọ Bẹnáyà+ àti Ábíátárì;+ Jóábù + sì ni olórí àwọn ọmọ ogun ọba.
28 Nígbà náà, Dáfídì kó gbogbo ìjòyè Ísírẹ́lì jọ sí Jerúsálẹ́mù, àwọn ni: àwọn ìjòyè ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àwọn olórí àwọn àwùjọ+ tó ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún,+ àwọn olórí tó ń bójú tó gbogbo ohun ìní àti àwọn ẹran ọ̀sìn ọba+ àti ti àwọn ọmọ rẹ̀+ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn ọkùnrin tó jẹ́ akíkanjú àti ọ̀jáfáfá.+ 2 Ìgbà náà ni Ọba Dáfídì dìde dúró, ó sì sọ pé:
“Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin arákùnrin mi àti ẹ̀yin èèyàn mi. Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi láti kọ́ ilé tó máa jẹ́ ibi ìsinmi fún àpótí májẹ̀mú Jèhófà, tí á sì jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ fún Ọlọ́run wa,+ mo sì ti ṣètò sílẹ̀ láti kọ́ ọ.+ 3 Àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún mi pé, ‘O ò ní kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ nítorí ọkùnrin ogun ni ọ́, o sì ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.’+ 4 Síbẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì yàn mí nínú gbogbo ilé bàbá mi láti di ọba lórí Ísírẹ́lì títí láé,+ nítorí ó yan Júdà ṣe aṣáájú,+ nínú gbogbo ilé Júdà, ó yan ilé bàbá mi,+ nínú gbogbo ọmọ bàbá mi, èmi ni ó fọwọ́ sí, láti fi mí jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+ 5 Nínú gbogbo àwọn ọmọ mi, torí àwọn ọmọ tí Jèhófà fún mi pọ̀,+ ó yan Sólómọ́nì+ ọmọ mi láti jókòó sórí ìtẹ́ ìjọba Jèhófà lórí Ísírẹ́lì.+
6 “Ó sọ fún mi pé, ‘Sólómọ́nì ọmọ rẹ ló máa kọ́ ilé mi àti àwọn àgbàlá mi, nítorí mo ti yàn án ṣe ọmọ mi, màá sì di bàbá rẹ̀.+ 7 Màá fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí láé+ tó bá pinnu láti máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìdájọ́+ mi mọ́, bí ó ti ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́.’ 8 Torí náà, mò ń sọ fún yín lójú gbogbo Ísírẹ́lì, ìyẹn ìjọ Jèhófà àti ní etí Ọlọ́run wa pé: Ẹ rí i pé ẹ mọ gbogbo àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́, kí ilẹ̀ dáradára+ náà lè di tiyín, kí ẹ sì lè fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún tó máa wà títí láé fún àwọn ọmọ yín.
9 “Ìwọ Sólómọ́nì ọmọ mi, mọ Ọlọ́run bàbá rẹ, kí o sì fi gbogbo ọkàn*+ àti inú dídùn* sìn ín, nítorí gbogbo ọkàn ni Jèhófà ń wá,+ ó sì ń fi òye mọ gbogbo èrò àti ìfẹ́ ọkàn.+ Tí o bá wá a, á jẹ́ kí o rí òun,+ àmọ́ tí o bá fi í sílẹ̀, á kọ̀ ẹ́ sílẹ̀ títí láé.+ 10 Ní báyìí, wò ó, Jèhófà ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé kan tó máa jẹ́ ibi mímọ́. Jẹ́ onígboyà kí o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.”
11 Lẹ́yìn náà, Dáfídì fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ní àwòrán ìkọ́lé+ ti ibi àbáwọlé*+ àti ti àwọn ilé rẹ̀, àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí, àwọn yàrá orí òrùlé, àwọn yàrá inú àti ti ilé ìbòrí ìpẹ̀tù.*+ 12 Ó fún un ní àwòrán ìkọ́lé gbogbo ohun tí a fi hàn án nípa ìmísí* nípa àwọn àgbàlá+ ilé Jèhófà, ti gbogbo àwọn yàrá ìjẹun tó yí i ká, ti àwọn ibi ìṣúra ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti ti àwọn ibi ìṣúra tí wọ́n ń kó àwọn ohun tí a sọ di* mímọ́+ sí; 13 bákan náà, ó sọ fún un nípa àwọn àwùjọ àwọn àlùfáà+ àti ti àwọn ọmọ Léfì, gbogbo iṣẹ́ tó jẹ́ iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà àti gbogbo nǹkan tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà; 14 ó tún fún un ní ìwọ̀n wúrà, wúrà gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n á fi ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ìsìn, ìwọ̀n gbogbo nǹkan èlò fàdákà àti gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n á fi ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ìsìn; 15 bákan náà, ó fún un ní ìwọ̀n àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà+ àti àwọn fìtílà wúrà wọn, ìwọ̀n oríṣiríṣi ọ̀pá fìtílà àti àwọn fìtílà wọn àti ìwọ̀n àwọn ọ̀pá fìtílà fàdákà, ti ọ̀pá fìtílà kọ̀ọ̀kan àti àwọn fìtílà rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lò wọ́n; 16 ó tún fún un ní ìwọ̀n wúrà àwọn tábìlì búrẹ́dì onípele,*+ ti tábìlì kọ̀ọ̀kan àti fàdákà tí wọ́n á fi ṣe àwọn tábìlì fàdákà, 17 ó fún un ní ìwọ̀n àwọn àmúga, àwọn abọ́, àwọn ṣágo ògidì wúrà àti ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn abọ́ kéékèèké wúrà+ àti ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan abọ́ kéékèèké fàdákà. 18 Ó tún fún un ní ìwọ̀n wúrà tí a yọ́ mọ́ fún pẹpẹ tùràrí+ àti fún àwòrán kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ ìyẹn, àwọn kérúbù+ wúrà tí wọ́n na ìyẹ́ apá wọn bo orí àpótí májẹ̀mú Jèhófà. 19 Dáfídì sọ pé: “Ọwọ́ Jèhófà wà pẹ̀lú mi, ó sì fún mi ní ìjìnlẹ̀ òye kí n lè kọ+ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ àwòrán ìkọ́lé+ náà sílẹ̀.”
20 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára kí o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Má bẹ̀rù, má sì jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run mi, wà pẹ̀lú rẹ.+ Kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀,+ àmọ́ ó máa wà pẹ̀lú rẹ títí gbogbo iṣẹ́ tó jẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà á fi parí. 21 Àwùjọ àwọn àlùfáà+ àti ti àwọn ọmọ Léfì+ nìyí fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́. O ní àwọn òṣìṣẹ́ tó ti múra tán, tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀jáfáfá láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí,+ o tún ní àwọn ìjòyè+ àti gbogbo àwọn èèyàn tó máa ṣe gbogbo ohun tí o bá ní kí wọ́n ṣe.”
29 Ọba Dáfídì sọ fún gbogbo ìjọ náà pé: “Sólómọ́nì ọmọ mi, ẹni tí Ọlọ́run yàn,+ jẹ́ ọ̀dọ́, kò ní ìrírí,*+ iṣẹ́ náà sì pọ̀, torí pé kì í ṣe tẹ́ńpìlì* èèyàn, àmọ́ ti Jèhófà Ọlọ́run ni.+ 2 Mo ti sa gbogbo ipá mi láti pèsè àwọn nǹkan sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run mi, mo ti pèsè wúrà fún iṣẹ́ ọnà wúrà, fàdákà fún iṣẹ́ ọnà fàdákà, bàbà fún iṣẹ́ ọnà bàbà, irin fún iṣẹ́ ọnà irin,+ àwọn igi fún iṣẹ́ ọnà igi,+ àwọn òkúta ónísì, àwọn òkúta tí wọ́n máa fi erùpẹ̀ tí a pò pọ̀ mọ, àwọn òkúta róbótó-róbótó lóríṣiríṣi àwọ̀, gbogbo oríṣiríṣi òkúta iyebíye àti òkúta alabásítà tó pọ̀ gan-an. 3 Bákan náà, nítorí ìfẹ́ tí mo ní fún ilé Ọlọ́run mi,+ mo fi wúrà àti fàdákà sílẹ̀ látinú àwọn ohun iyebíye mi+ fún ilé Ọlọ́run mi, láfikún sí gbogbo ohun tí mo ti fi sílẹ̀ fún ilé mímọ́ náà, 4 títí kan ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) tálẹ́ńtì* wúrà Ófírì+ àti ẹgbẹ̀rún méje (7,000) tálẹ́ńtì fàdákà tí a yọ́ mọ́, láti fi bo ògiri àwọn ilé náà, 5 wúrà fún iṣẹ́ ọnà wúrà àti fàdákà fún iṣẹ́ ọnà fàdákà àti fún gbogbo iṣẹ́ tí àwọn oníṣẹ́ ọnà máa ṣe. Ní báyìí, ta ló fẹ́ mú ẹ̀bùn wá fún Jèhófà lónìí?”+
6 Nítorí náà, àwọn olórí àwọn agbo ilé, àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ pẹ̀lú àwọn olórí tó ń bójú tó iṣẹ́ ọba+ jáde wá tinú-tinú. 7 Àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́ nìyí: ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) tálẹ́ńtì wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) owó dáríkì,* ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ńtì fàdákà, ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) tálẹ́ńtì bàbà àti ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) tálẹ́ńtì irin. 8 Gbogbo àwọn tó ní òkúta iyebíye kó wọn wá sí ibi ìṣúra ilé Jèhófà lábẹ́ àbójútó Jéhíélì+ ọmọ Gẹ́ṣónì.+ 9 Inú àwọn èèyàn náà dùn pé wọ́n mú ọrẹ wá tinútinú, nítorí pé gbogbo ọkàn+ ni wọ́n fi mú ọrẹ náà wá fún Jèhófà, inú Ọba Dáfídì pẹ̀lú sì dùn gan-an.
10 Nígbà náà, Dáfídì yin Jèhófà lójú gbogbo ìjọ náà. Dáfídì sọ pé: “Ìyìn ni fún ọ, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì baba wa, títí láé àti láéláé.* 11 Jèhófà, tìrẹ ni títóbi+ àti agbára ńlá+ àti ẹwà àti ògo àti ọlá ńlá,*+ nítorí gbogbo ohun tó wà ní ọ̀run àti ní ayé jẹ́ tìrẹ.+ Jèhófà, tìrẹ ni ìjọba.+ Ìwọ ni Ẹni tó fi ara rẹ̀ ṣe olórí lórí ohun gbogbo. 12 Ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àti ògo ti wá,+ o sì ń ṣàkóso ohun gbogbo,+ ọwọ́ rẹ ni agbára+ àti títóbi+ wà, ọwọ́ rẹ ló lè sọni di ńlá,+ òun ló sì lè fúnni lágbára.+ 13 Ní báyìí, Ọlọ́run wa, a dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, a sì yin orúkọ rẹ ológo.
14 “Síbẹ̀, ta ni mí, ta sì ni àwọn èèyàn mi, tí a fi máa láǹfààní láti ṣe ọrẹ àtinúwá bí irú èyí? Nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, ohun tó ti ọwọ́ rẹ wá ni a sì fi fún ọ. 15 Nítorí àjèjì àti àlejò ni a jẹ́ níwájú rẹ, bí gbogbo àwọn baba ńlá wa ti jẹ́.+ Nítorí àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé da bí òjìji,+ kò sí ìrètí kankan. 16 Jèhófà Ọlọ́run wa, gbogbo ọrọ̀ yìí tí a ti kó jọ láti fi kọ́ ilé fún ìwọ àti orúkọ mímọ́ rẹ, ọwọ́ rẹ ni ó ti wá, tìrẹ sì ni gbogbo rẹ̀. 17 Ọlọ́run mi, mo mọ̀ dáadáa pé o máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn+ àti pé o fẹ́ràn ìwà títọ́.*+ Nínú òótọ́* ọkàn ni mo fínnú-fíndọ̀ pèsè gbogbo nǹkan yìí, ayọ̀ mi sì kún láti rí àwọn èèyàn rẹ tó wá síbí láti ṣe ọrẹ àtinúwá fún ọ. 18 Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ máa ní irú ẹ̀mí àti èrò yìí nínú ọkàn wọn títí láé, kí o sì darí ọkàn wọn sọ́dọ̀ rẹ.+ 19 Kí o fún Sólómọ́nì ọmọ mi ní ọkàn pípé,*+ kí ó lè máa pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́+ àti àwọn ìránnilétí rẹ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ, kí ó lè ṣe gbogbo nǹkan yìí, kí ó sì kọ́ tẹ́ńpìlì* tí mo ti pèsè àwọn nǹkan sílẹ̀ fún.”+
20 Dáfídì wá sọ fún gbogbo ìjọ náà pé: “Ní báyìí, ẹ yin Jèhófà Ọlọ́run yín.” Gbogbo ìjọ náà sì yin Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, wọ́n tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀ fún Jèhófà àti fún ọba. 21 Wọ́n ń rú àwọn ẹbọ sí Jèhófà, wọ́n sì ń rú àwọn ẹbọ sísun+ sí Jèhófà ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ ọmọ màlúù, ẹgbẹ̀rún (1,000) àgbò, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti àwọn ọrẹ ohun mímu+ wọn; àwọn ẹbọ tí wọ́n rú nítorí gbogbo Ísírẹ́lì pọ̀ gan-an.+ 22 Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu níwájú Jèhófà ní ọjọ́ yẹn tìdùnnútìdùnnú,+ wọ́n fi Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì jẹ ọba lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì fòróró yàn án níwájú Jèhófà láti jẹ́ aṣáájú,+ bákan náà wọ́n yan Sádókù láti jẹ́ àlùfáà.+ 23 Sólómọ́nì jókòó sórí ìtẹ́ Jèhófà+ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò Dáfídì bàbá rẹ̀, ó ṣàṣeyọrí, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń ṣègbọràn sí i. 24 Gbogbo àwọn ìjòyè,+ àwọn jagunjagun tó lákíkanjú+ àti gbogbo àwọn ọmọ Ọba Dáfídì+ fi ara wọn sábẹ́ Ọba Sólómọ́nì. 25 Jèhófà sọ Sólómọ́nì di ẹni ńlá tó ta yọ lójú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì fi iyì ọba dá a lọ́lá débi pé kò sí ọba kankan ní Ísírẹ́lì tó nírú iyì bẹ́ẹ̀ rí.+
26 Bí Dáfídì ọmọ Jésè ṣe jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì nìyẹn, 27 gbogbo ọdún* tó fi jọba lórí Ísírẹ́lì jẹ́ ogójì (40) ọdún. Ó fi ọdún méje jọba+ ní Hébúrónì, ó sì fi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) jọba+ ní Jerúsálẹ́mù. 28 Ó dàgbà, ó darúgbó+ kó tó kú, ẹ̀mí* rẹ̀ gùn dáadáa, ó ní ọrọ̀ àti ògo; Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+ 29 Ní ti ìtàn Ọba Dáfídì láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó wà lákọsílẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì aríran àti ti wòlíì Nátánì+ àti ti Gádì+ olùríran 30 pẹ̀lú gbogbo ìjọba rẹ̀ àti agbára rẹ̀ àti àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i àti sí Ísírẹ́lì àti sí gbogbo ìjọba àwọn ilẹ̀ tó yí i ká nígbà ayé rẹ̀.
Àwọn tó tẹ̀ lé e yìí ni àwọn ọmọ Árámù. Wo Jẹ 10:23.
Ó túmọ̀ sí “Pín Sọ́tọ̀.”
Tàbí “aráyé.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “pápá.”
Séríkí jẹ́ olóyè láàárín ẹ̀yà kan.
Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Mú Àjálù Wá; Ẹni Tó Mú Ìtanù Wá.” Ní Joṣ 7:1, wọ́n tún pè é ní Ákánì.
Tàbí “wàhálà; ìtanù.”
Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Wọ́n tún pè é ní Kélẹ́bù ní ẹsẹ 18, 19, 42.
Tí wọ́n pè ní Kélúbáì ní ẹsẹ 9.
Tàbí “àwọn ìlú tó yí i ká.”
Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Wọ́n tún pè é ní Kélúbáì ní ẹsẹ 9.
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù lè túmọ̀ sí ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí àtọmọdọ́mọ.
Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ní àwọn ibì kan nínú orí yìí, “bàbá” lè túmọ̀ sí ẹni tí ó tẹ ìlú kan dó.
Orúkọ Jábésì ṣeé ṣe kó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “ìrora.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ó túmọ̀ sí “Àfonífojì Àwọn Oníṣẹ́ Ọnà.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Bitáyà ní ẹsẹ 18 ló ń tọ́ka sí.
Tàbí “bàbá.”
Tàbí “àwọn ọ̀rọ̀ yìí wá látinú àṣà àtijọ́.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù lè túmọ̀ sí ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí àtọmọdọ́mọ.
Tàbí “sọ ibùsùn bàbá rẹ̀ di ẹlẹ́gbin.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù lè túmọ̀ sí ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí àtọmọdọ́mọ.
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Ìyẹn, Jèróbóámù Kejì.
Ní Héb., “wọ́n mọ bí a ṣe ń fi okùn sí ọrun.”
Tàbí “ọkàn èèyàn.”
Ní Héb., “ru ẹ̀mí Púlì ọba Ásíríà sókè.”
Ní Héb., “ọmọkùnrin.”
Wọ́n tún pè é ní Gẹ́ṣónì ní ẹsẹ 1.
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù lè túmọ̀ sí ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí àtọmọdọ́mọ.
Tàbí “Àtọmọdọ́mọ.”
Tàbí “Àtọmọdọ́mọ.”
Ìyẹn, “ọmọ Léfì bíi tiẹ̀.”
Ní Héb., “ni a fi lélẹ̀.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù lè túmọ̀ sí ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí àtọmọdọ́mọ.
Tàbí “àgọ́ olódi.”
Tàbí kó jẹ́, “ìlú,” èyí bá Joṣ 21:13 mu.
Tàbí “ṣẹ́ kèké láti fún.”
Tàbí kó jẹ́, “ìlú,” èyí bá Joṣ 21:21 mu.
Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “olórí.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù lè túmọ̀ sí ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí àtọmọdọ́mọ.
Ó túmọ̀ sí “Pẹ̀lú Àjálù.”
Tàbí “Jèhóṣúà,” ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Tàbí kó jẹ́, “Gásà,” síbẹ̀ kì í ṣe Gásà tó wà ní Filísíà.
Wọ́n tún pè é ní Ṣómérì ní ẹsẹ 32.
Ó lè jẹ́ ìkan náà pẹ̀lú “Hótámù” ní ẹsẹ 32.
Ní Héb., “pápá.”
Tàbí kó jẹ́, “lẹ́yìn tó lé àwọn ìyàwó rẹ̀, Húṣímù àti Báárà kúrò.”
Tàbí “àwọn ìlú tó yí i ká.”
Wọ́n tún ń pè é ní Íṣí-bóṣétì.
Wọ́n tún ń pè é ní Méfíbóṣétì.
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù lè túmọ̀ sí ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí àtọmọdọ́mọ.
Ní Héb., “mọ ọrun tẹ̀.”
Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”
Ní Héb., “olórí agbo ilé bàbá wọn.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Ní Héb., “alágbára.”
Tàbí “yàrá ìjẹun.”
Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.
Tàbí “yàrá ìjẹun.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù lè túmọ̀ sí ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí àtọmọdọ́mọ.
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “ṣe mí ṣúkaṣùka.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Ní Héb., “Egungun àti ara.”
Ní Héb., “ìwọ ló ń mú Ísírẹ́lì jáde tí o sì ń mú wọn wọlé.”
Ní Héb., “olórí.”
Tàbí “Mílò.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “iyẹ̀pẹ̀ tí a kó jọ gègèrè.”
Tàbí “ìgbàlà.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “fọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ọmọ ọkùnrin kan tó lákíkanjú.”
Ó ga tó nǹkan bíi mítà 2.23 (ẹsẹ̀ bàtà 7.3) Wo Àfikún B14.
Tàbí “olófì.”
Ní Héb., “Ọrun.”
Ní Héb., “ẹ̀mí wọ Ámásáì láṣọ.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Tàbí “gbogbo àwọn tó dara pọ̀ mọ́ Dáfídì ni kì í ṣe ọlọ́kàn méjì.”
Ní Héb., “ni ọkàn wọn ṣọ̀kan láti.”
Tàbí “láti Ṣíhórì.”
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Tàbí kó jẹ́, “láàárín.”
Tàbí “aro.”
Tàbí “inú Dáfídì bà jẹ́.”
Ó túmọ̀ sí “Ìbínú Ru sí Úsà.”
Tàbí “àwọn tó ń mọ ògiri.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ó túmọ̀ sí “Ọ̀gá Àwọn Tó Ń Ya Luni.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “aro.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “wíńdò.”
Ní Héb., “rántí.”
Tàbí “aro.”
Tàbí “kọ orin fún un.”
Tàbí kó jẹ́, “sọ nípa.”
Tàbí “ibi tó wà.”
Tàbí “àtọmọdọ́mọ.” Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “ọ̀rọ̀ tó pa láṣẹ.”
Tàbí “iyì.”
Tàbí “jọ́sìn.”
Tàbí kó jẹ́, “nítorí ògo ìjẹ́mímọ́ rẹ̀.”
Tàbí “Ilẹ̀ tó ń méso jáde.”
Tàbí “kò ṣeé mì; a kì yóò mú kó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”
Tàbí “ó ti dé láti.”
Tàbí “yọ̀ nínú ìyìn rẹ.”
Tàbí “Láti ayérayé dé ayérayé.”
Tàbí “Kó rí bẹ́ẹ̀!”
Tàbí “kọrin sí.”
Tàbí “ààfin.”
Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “láti ibi tí àgọ́ kan wà dé òmíràn àti láti ibi gbígbé kan dé òmíràn.”
Ní Héb., “ké.”
Ní Héb., “tán wọn lókun.”
Tàbí “sọ ìdílé rẹ di ìdílé tó ń jọba.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “ẹni tó wà níbi gíga.”
Tàbí “bá ìfẹ́ rẹ mu.”
Tàbí “fìdí múlẹ̀.”
Tàbí “sọ ìdílé rẹ̀ di ìdílé tó ń jọba.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “pátì.”
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “gba Dáfídì là.”
Tàbí “apata ribiti.”
Tàbí “gba Dáfídì là.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “Aramu-náháráímù.”
Ní Héb., “sí ọwọ́.”
Ìyẹn, odò Yúfírétì.
Ìyẹn, nígbà ìrúwé.
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “olófì.”
Tàbí kó jẹ́, “alátakò.”
Tàbí “kẹ́dùn.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “wíìtì.”
Ní Héb., “Fi.”
Ní Héb., “ohun tó bá dára lójú rẹ̀.”
Tàbí “wíìtì.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Irú èyí tí àwọn káfíńtà máa ń lò.
Tàbí “ẹlẹgẹ́ sì ni.”
Ní Héb., “ìsinmi.”
Látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “Àlàáfíà.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Ní Héb., “darúgbó, tí ọjọ́ rẹ̀ sì ti kún rẹ́rẹ́.”
Tàbí “pín.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “arákùnrin.”
Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.
Tàbí “aro.”
Ní Héb., “ìwo rẹ̀.”
Tàbí “yà sí.”
Ní Héb., “ìbínú wà lórí Ísírẹ́lì.”
Tàbí “ibi ìṣúra.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
Tàbí “ọ̀rẹ́ àfinúhàn.”
Tàbí “ọkàn tó pa pọ̀.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “ìmúratán.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “ilé ètùtù.”
Ní Héb., “ẹ̀mí.”
Tàbí “yà sí.”
Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.
Tàbí “ẹlẹgẹ́ sì ni.”
Tàbí “ilé ńlá; ààfin.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Dáríkì jẹ́ owó ẹyọ wúrà ilẹ̀ Páṣíà. Wo Àfikún B14.
Tàbí “láti ayérayé dé ayérayé.”
Tàbí “iyì.”
Tàbí “òdodo; ìdúróṣinṣin.”
Tàbí “ìdúróṣinṣin.”
Tàbí “ọkàn tó pa pọ̀.”
Tàbí “ilé ńlá; ààfin.”
Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”
Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”