SEKARÁYÀ
1 Ní oṣù kẹjọ, ọdún kejì ìjọba Dáríúsì,+ Jèhófà sọ fún wòlíì Sekaráyà*+ ọmọ Berekáyà ọmọ Ídò pé: 2 “Jèhófà bínú gan-an sí àwọn baba yín.+
3 “Sọ fún àwọn èèyàn yìí pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “‘Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, ‘èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”’
4 “‘Ẹ má dà bí àwọn baba yín, tí àwọn wòlíì àtijọ́ kéde fún pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi ìwà búburú yín sílẹ̀* kí ẹ sì jáwọ́ nínú iṣẹ́ ibi.’”’+
“‘Àmọ́ wọn ò gbọ́, wọn ò sì fetí sí ohun tí mo sọ,’+ ni Jèhófà wí.
5 “‘Ibo wá ni àwọn baba yín wà báyìí? Àwọn wòlíì yẹn ńkọ́, ṣé wọ́n wà títí láé? 6 Àmọ́ ohun tí mo sọ àti àṣẹ tí mo pa fún àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì, ó ṣẹ sí àwọn baba yín lára, àbí kò ṣẹ?’+ Torí náà, wọ́n pa dà sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì sọ pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti fi ìyà jẹ wá nítorí àwọn ọ̀nà wa àti àwọn ìṣe wa, bó ṣe pinnu láti ṣe.’”+
7 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, ìyẹn oṣù Ṣébátì,* ní ọdún kejì ìjọba Dáríúsì,+ Jèhófà bá wòlíì Sekaráyà ọmọ Berekáyà ọmọ Ídò sọ̀rọ̀. Sekaráyà sọ pé: 8 “Mo rí ìran kan ní òru. Ọkùnrin kan ń gun ẹṣin pupa, ó sì dúró láàárín àwọn igi mátílì tó wà ní àfonífojì; ẹṣin pupa, ẹṣin pupa rẹ́súrẹ́sú àti ẹṣin funfun sì wà lẹ́yìn rẹ̀.”
9 Torí náà, mo sọ pé: “Olúwa mi, àwọn wo nìyí?”
Áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ dá mi lóhùn pé: “Màá fi ẹni tí wọ́n jẹ́ hàn ọ́.”
10 Lẹ́yìn náà, ọkùnrin tó dúró láàárín àwọn igi mátílì náà sọ pé: “Àwọn yìí ni Jèhófà rán jáde pé kí wọ́n rìn káàkiri ayé.” 11 Wọ́n sì sọ fún áńgẹ́lì Jèhófà tó dúró láàárín àwọn igi mátílì náà pé: “A ti rìn káàkiri ayé, a sì rí i pé gbogbo ayé pa rọ́rọ́, kò sí wàhálà kankan.”+
12 Torí náà, áńgẹ́lì Jèhófà sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kí o tó ṣàánú Jerúsálẹ́mù àti àwọn ìlú Júdà+ tí o ti bínú sí fún àádọ́rin (70) ọdún báyìí?”+
13 Jèhófà fi ọ̀rọ̀ tó dáa àti ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú dá áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn. 14 Áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì sọ fún mi pé: “Kéde pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo ní ìtara tó pọ̀ fún Jerúsálẹ́mù àti fún Síónì.+ 15 Inú bí mi gan-an sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ara tù,+ torí mi ò bínú púpọ̀ sí àwọn èèyàn mi,+ àmọ́ wọ́n dá kún àjálù náà.”’+
16 “Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘“Èmi yóò pa dà ṣàánú Jerúsálẹ́mù,”+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, “wọn yóò kọ́ ilé mi sí ibẹ̀,+ wọn yóò sì na okùn ìdíwọ̀n sórí Jerúsálẹ́mù.”’+
17 “Kéde lẹ́ẹ̀kan sí i pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ìwà rere máa pa dà kún àkúnwọ́sílẹ̀ ní àwọn ìlú mi; Jèhófà yóò sì pa dà tu Síónì nínú,+ yóò sì tún Jerúsálẹ́mù yàn.”’”+
18 Mo wá wòkè, mo sì rí ìwo mẹ́rin.+ 19 Torí náà, mo bi áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Kí làwọn nǹkan yìí?” Ó dáhùn pé: “Àwọn ìwo yìí ló fọ́n Júdà,+ Ísírẹ́lì+ àti Jerúsálẹ́mù ká.”+
20 Jèhófà wá fi àwọn oníṣẹ́ ọnà mẹ́rin hàn mí. 21 Mo bi í pé: “Kí ni àwọn yìí ń bọ̀ wá ṣe?”
Ó sọ pé: “Àwọn ìwo yìí ló fọ́n Júdà ká débi tí kò fi sí ẹnì kankan tó lè gbé orí sókè. Àwọn yìí ní tiwọn yóò wá láti dẹ́rù bà wọ́n, kí wọ́n lè ṣẹ́ ìwo àwọn orílẹ̀-èdè tó gbé ìwo wọn sókè sí ilẹ̀ Júdà, láti fọ́n ọn ká.”
2 Mo wòkè, mo sì rí ọkùnrin kan tó mú okùn ìdíwọ̀n+ dání. 2 Torí náà, mo bi í pé: “Ibo lò ń lọ?”
Ó fèsì pé: “Mo fẹ́ lọ wọn Jerúsálẹ́mù kí n lè mọ bó ṣe fẹ̀ tó àti bó ṣe gùn tó.”+
3 Wò ó! áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, áńgẹ́lì míì sì wá pàdé rẹ̀. 4 Ó wá sọ fún un pé: “Sáré lọ síbẹ̀ yẹn, kí o sì sọ fún ọkùnrin yẹn pé, ‘“Wọn yóò gbé inú Jerúsálẹ́mù+ bí ìgbèríko gbalasa,* nítorí gbogbo èèyàn àti ẹran ọ̀sìn tó máa wà nínú rẹ̀.”+ 5 Jèhófà kéde pé, “Èmi yóò di ògiri iná fún un yí ká,+ màá sì mú kí ògo mi wà láàárín rẹ̀.”’”+
6 Jèhófà kéde pé, “Ẹ wá! Ẹ wá! Ẹ sá kúrò ní ilẹ̀ àríwá.”+
“Torí mo ti fọ́n yín káàkiri,”*+ ni Jèhófà wí.
7 “Wá, Síónì! Sá àsálà, ìwọ tí ń gbé pẹ̀lú ọmọbìnrin Bábílónì.+ 8 Torí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, lẹ́yìn tí a ti yìn ín lógo, ó rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tó ń kó ẹrù yín,+ pé; ‘Ẹni tó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú* mi.+ 9 Wọ́n á rí ìbínú mi, àwọn ìránṣẹ́ wọn yóò sì kó ẹrù wọn.’+ Ó sì dájú pé ẹ máa mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló rán mi.
10 “Kígbe ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì;+ torí mò ń bọ̀,+ èmi yóò sì máa gbé láàárín rẹ,”+ ni Jèhófà wí. 11 “Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò fara mọ́ Jèhófà ní ọjọ́ náà,+ wọ́n á sì di èèyàn mi; èmi yóò sì máa gbé láàárín yín.” Ẹ ó sì mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló rán mi sí yín. 12 Jèhófà yóò gba Júdà bí ìpín rẹ̀ lórí ilẹ̀ mímọ́, yóò sì tún Jerúsálẹ́mù yàn.+ 13 Gbogbo aráyé,* ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà torí ó ń gbé ìgbésẹ̀ láti ibi mímọ́ tó ń gbé.
3 Ó sì fi Jóṣúà + tó jẹ́ àlùfáà àgbà hàn mí, ó dúró níwájú áńgẹ́lì Jèhófà, Sátánì+ sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kó lè ta kò ó. 2 Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún Sátánì pé: “Kí Jèhófà bá ọ wí, ìwọ Sátánì,+ bẹ́ẹ̀ ni, kí Jèhófà, ẹni tó yan Jerúsálẹ́mù+ bá ọ wí! Ṣebí ẹni yìí ni igi tó ń jó tí wọ́n yọ kúrò nínú iná?”
3 Aṣọ ọrùn Jóṣúà dọ̀tí, ó sì dúró níwájú áńgẹ́lì náà. 4 Áńgẹ́lì náà sọ fún àwọn tó dúró níwájú rẹ̀ pé: “Ẹ bọ́ aṣọ ìdọ̀tí tó wà lọ́rùn rẹ̀.” Ó wá sọ fún un pé: “Wò ó, mo ti mú ẹ̀ṣẹ̀* rẹ kúrò, ìwọ yóò sì wọ aṣọ tó mọ́.”*+
5 Torí náà, mo sọ pé: “Ẹ fi láwàní tó mọ́ wé e lórí.”+ Wọ́n fi láwàní náà wé e lórí, wọ́n sì wọ aṣọ fún un; áńgẹ́lì Jèhófà sì dúró nítòsí. 6 Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: 7 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Tí o bá rìn ní àwọn ọ̀nà mi, tí o sì ń ṣe ojúṣe rẹ sí mi, ìwọ yóò di adájọ́ ní ilé mi,+ ìwọ yóò sì máa bójú tó* àwọn àgbàlá mi; èmi yóò sì fún ọ láǹfààní bíi ti àwọn tó dúró síbí.’
8 “‘Àlùfáà Àgbà Jóṣúà, jọ̀ọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ àti àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n jókòó níwájú rẹ, torí àwọn ọkùnrin yìí jẹ́ àmì; wò ó! mò ń mú ìránṣẹ́ mi+ tó ń jẹ́ Èéhù+ bọ̀! 9 Wo òkúta tí mo fi síwájú Jóṣúà! Ojú méje ló wà lára òkúta náà; èmi yóò kọ nǹkan sí ara rẹ̀, èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan ṣoṣo,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.+
10 “‘Ní ọjọ́ yẹn, kálukú yín yóò pe aládùúgbò rẹ̀ pé kó wá sí abẹ́ àjàrà àti abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ òun,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”+
4 Áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pa dà wá, ó sì jí mi, bí ìgbà tí wọ́n jí ẹni tó ń sùn. 2 Ó wá bi mí pé: “Kí lo rí?”
Mo sì sọ pé: “Wò ó! mo rí ọ̀pá fìtílà kan tí wọ́n fi wúrà ṣe látòkèdélẹ̀,+ abọ́ kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà méje wà lórí rẹ̀,+ àní méje, àwọn fìtílà orí rẹ̀ sì ní ọ̀pá méje. 3 Igi ólífì méjì sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ ọ̀kan ní apá ọ̀tún abọ́ náà, èkejì ní apá òsì rẹ̀.”
4 Lẹ́yìn náà, mo bi áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Olúwa mi, kí làwọn nǹkan yìí túmọ̀ sí?” 5 Áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ bá bi mí pé: “Ṣé o ò mọ ohun tí àwọn nǹkan yìí túmọ̀ sí ni?”
Mo fèsì pé: “Mi ò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.”
6 Ó wá sọ fún mi pé: “Ohun tí Jèhófà sọ fún Serubábélì nìyí: ‘“Kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun tàbí nípasẹ̀ agbára,+ bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 7 Báwo ni tìẹ ṣe jẹ́ ìwọ òkè ńlá? Wàá di ilẹ̀ pẹrẹsẹ*+ níwájú Serubábélì.+ Òun yóò mú òkúta tó wà lókè jáde bí àwọn èèyàn ṣe ń kígbe pé: “Ó mà dára o! Ó mà dára o!”’”
8 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 9 “Serubábélì ló fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí,+ ọwọ́ rẹ̀ náà ni yóò sì parí rẹ̀.+ Ẹ ó sì mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló rán mi sí yín. 10 Ta ló pẹ̀gàn ọjọ́ tí nǹkan bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́?*+ Inú wọn á dùn, wọ́n á sì rí okùn ìwọ̀n* ní ọwọ́ Serubábélì. Àwọn méje yìí ni ojú Jèhófà, tó ń wò káàkiri ayé.”+
11 Mo wá bi í pé: “Kí ni igi ólífì méjì yìí túmọ̀ sí, tó wà ní apá ọ̀tún àti apá òsì ọ̀pá fìtílà náà?”+ 12 Mo tún bi í lẹ́ẹ̀kejì pé: “Kí ni ìdì méjì ẹ̀ka* igi ólífì náà túmọ̀ sí, tó ní òpó wúrà méjì tí òróró wúrà ń ṣàn jáde láti inú rẹ̀?”
13 Ó wá bi mí pé: “Ṣé o ò mọ ohun tí àwọn nǹkan yìí túmọ̀ sí ni?”
Mo dáhùn pé: “Mi ò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.”
14 Ó sọ pé: “Àwọn yìí ni àwọn ẹni àmì òróró méjì tí wọ́n ń dúró ní ẹ̀gbẹ́ Olúwa gbogbo ayé.”+
5 Mo tún wòkè, mo sì rí àkájọ ìwé kan tó ń fò. 2 Ó bi mí pé: “Kí lo rí?”
Mo fèsì pé: “Mo rí àkájọ ìwé tó ń fò, tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́,* tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.”
3 Ó wá sọ fún mi pé: “Èyí ni ègún tó ń lọ sí gbogbo ayé, bí wọ́n ṣe kọ ọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan ìwé náà, torí gbogbo ẹni tó ń jalè+ ti lọ láìjìyà; bí wọ́n sì ṣe kọ ọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kejì, torí gbogbo ẹni tó ń búra+ ti lọ láìjìyà. 4 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, ‘Mo ti rán an jáde, yóò sì wọnú ilé olè àti ilé ẹni tó ń fi orúkọ mi búra èké; yóò wà nínú ilé náà, yóò sì jẹ ẹ́ run, pẹ̀lú àwọn ẹ̀là gẹdú àti òkúta rẹ̀.’”
5 Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ wá síwájú, ó sì sọ fún mi pé: “Jọ̀ọ́ wòkè, kí o sì wo ohun tó ń jáde lọ.”
6 Mo wá bi í pé: “Kí ni?”
Ó fèsì pé: “Agbọ̀n tó dà bí òṣùwọ̀n eéfà* ló ń jáde lọ.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí wọ́n ṣe rí ní gbogbo ayé nìyẹn.” 7 Mo sì rí i tí wọ́n ṣí ìdérí roboto tí wọ́n fi òjé ṣe, obìnrin kan sì wà nínú agbọ̀n náà tó jókòó. 8 Áńgẹ́lì náà wá sọ pé: “Ìwà Burúkú nìyí.” Ó tì í pa dà sínú agbọ̀n náà, ó sì fi ìdérí tí wọ́n fi òjé ṣe náà dé e.
9 Lẹ́yìn náà, mo wòkè, mo sì rí obìnrin méjì tí wọ́n ń bọ̀, tí wọ́n ń yára fò nínú afẹ́fẹ́. Ìyẹ́ wọn dà bíi ti ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n sì gbé agbọ̀n náà kúrò nílẹ̀.* 10 Mo wá bi áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Ibo ni wọ́n ń gbé agbọ̀n tó dà bí òṣùwọ̀n eéfà yẹn lọ?”
11 Ó fèsì pé: “Ilẹ̀ Ṣínárì*+ ni wọ́n ń gbé e lọ, kí wọ́n lè kọ́lé fún obìnrin náà; tí wọ́n bá sì ti kọ́ ọ tán, wọn yóò fi í síbẹ̀, ní àyè rẹ̀.”
6 Mo tún wòkè, mo sì rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin mẹ́rin tó ń bọ̀ láti àárín òkè méjì, òkè bàbà sì ni àwọn òkè náà. 2 Àwọn ẹṣin pupa ló ń fa kẹ̀kẹ́ àkọ́kọ́, àwọn ẹṣin dúdú ló sì ń fa kẹ̀kẹ́ kejì.+ 3 Àwọn ẹṣin funfun ló ń fa kẹ̀kẹ́ kẹta, àwọn ẹṣin aláwọ̀ tó-tò-tó àti kàlákìnní ló sì ń fa kẹ̀kẹ́ kẹrin.+
4 Mo bi áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Kí làwọn nǹkan yìí, olúwa mi?”
5 Áńgẹ́lì náà dá mi lóhùn pé: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí+ mẹ́rin ti ọ̀run tó ń jáde lọ lẹ́yìn tí wọ́n dúró níwájú Olúwa gbogbo ayé.+ 6 Èyí* tí àwọn ẹṣin dúdú ń fà jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá;+ èyí tí àwọn ẹṣin funfun ń fà lọ sí ìkọjá òkun; àwọn aláwọ̀ tó-tò-tó sì ń lọ sí ilẹ̀ gúúsù. 7 Ara sì ń yá àwọn ẹṣin aláwọ̀ kàlákìnní náà láti jáde lọ kí wọ́n lè rìn káàkiri ayé.” Áńgẹ́lì náà wá sọ pé: “Ẹ lọ, ẹ rìn káàkiri ayé.” Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn káàkiri ayé.
8 Ó wá pè mí, ó sì sọ pé: “Wò ó, àwọn tó ń jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá ti rọ ẹ̀mí Jèhófà lójú ní ilẹ̀ náà.”
9 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 10 “Gba ohun tí Hélídáì, Tóbíjà àti Jedáyà mú wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn; ní ọjọ́ yẹn, kí ìwọ àti àwọn èèyàn yìí tó wá láti Bábílónì lọ sí ilé Jòsáyà ọmọ Sefanáyà. 11 Kí o fi fàdákà àti wúrà ṣe adé,* kí o sì fi dé orí Àlùfáà Àgbà Jóṣúà+ ọmọ Jèhósádákì. 12 Kí o sì sọ fún un pé,
“‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ọkùnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Èéhù+ rèé. Yóò hù jáde láti àyè rẹ̀, yóò sì kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà.+ 13 Òun ni yóò kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà, òun ni iyì máa tọ́ sí. Yóò jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, yóò sì ṣàkóso, yóò sì tún jẹ́ àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀,+ ọ̀kan kò sì ní pa èkejì lára.* 14 Adé* náà yóò jẹ́ ohun ìrántí fún Hélémù, Tóbíjà, Jedáyà+ àti Hénì ọmọ Sefanáyà nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà. 15 Àwọn tó wà lọ́nà jíjìn yóò wá, wọ́n sì máa wà lára àwọn tí yóò kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà.” Ẹ ó sì mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló rán mi sí yín. Yóò sì rí bẹ́ẹ̀, tí ẹ bá fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín.’”
7 Ní ọdún kẹrin tí Ọba Dáríúsì ti ń ṣàkóso, Jèhófà bá Sekaráyà+ sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsàn-án, ìyẹn oṣù Kísíléfì.* 2 Àwọn ará Bẹ́tẹ́lì rán Ṣárésà àti Regemu-mélékì àti àwọn èèyàn rẹ̀ kí wọ́n lè bẹ Jèhófà pé kó ṣojúure sí wọn,* 3 wọ́n ń sọ fún àwọn àlùfáà ilé* Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun àti fún àwọn wòlíì pé: “Ṣé kí n sunkún ní oṣù karùn-ún,+ kí n má sì jẹun, bí mo ti ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún?”
4 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 5 “Sọ fún gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà àti àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ gbààwẹ̀, tí ẹ sì pohùn réré ẹkún ní oṣù karùn-ún àti oṣù keje+ fún àádọ́rin (70) ọdún,+ ṣé torí mi lẹ ṣe gbààwẹ̀ lóòótọ́? 6 Nígbà tí ẹ jẹ tí ẹ sì mu, ṣebí torí ara yín lẹ ṣe ń jẹ tí ẹ sì ń mu? 7 Ṣé kò yẹ kí ẹ ṣe ohun tí Jèhófà sọ nípasẹ̀ àwọn wòlíì àtijọ́,+ nígbà tí àwọn èèyàn ń gbé ní Jerúsálẹ́mù àti àwọn ìlú tó yí i ká, tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà àti nígbà tí àwọn èèyàn ń gbé ní Négébù àti Ṣẹ́fẹ́là?’”
8 Jèhófà tún sọ fún Sekaráyà pé: 9 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ẹ dá ẹjọ́ òdodo,+ kí ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín má yẹ̀,+ kí ẹ sì máa ṣàánú ara yín. 10 Ẹ má lu opó tàbí ọmọ aláìníbaba* ní jìbìtì,+ ẹ má lu àjèjì tàbí aláìní ní jìbìtì,+ ẹ má sì gbèrò ibi sí ara yín nínú ọkàn yín.’+ 11 Àmọ́ wọn ò fetí sílẹ̀,+ agídí wọn mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí mi,+ wọ́n sì di etí wọn kí wọ́n má bàa gbọ́.+ 12 Wọ́n mú kí ọkàn wọn le bíi dáyámọ́ǹdì,*+ wọn ò sì tẹ̀ lé òfin* àti ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun fi ẹ̀mí rẹ̀ sọ nípasẹ̀ àwọn wòlíì àtijọ́.+ Torí náà, inú bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun gan-an.”+
13 “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, ‘Bí wọn ò ṣe fetí sílẹ̀ nígbà tí mo* pè wọ́n,+ bẹ́ẹ̀ náà ni mi ò ní fetí sílẹ̀ tí wọ́n bá pè.+ 14 Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn ò mọ̀.+ Ilẹ̀ náà di ahoro lẹ́yìn wọn, ẹnì kankan ò kọjá níbẹ̀, ẹnì kankan ò sì pa dà síbẹ̀;+ torí wọ́n ti sọ ilẹ̀ dáradára náà di ohun tó ń dẹ́rù bani.’”
8 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “‘Màá ní ìtara tó pọ̀ fún Síónì,+ tìbínútìbínú sì ni màá fi ní ìtara fún un,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”
3 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Èmi yóò pa dà sí Síónì,+ èmi yóò sì máa gbé ní Jerúsálẹ́mù;+ wọ́n á máa pe Jerúsálẹ́mù ní ìlú òtítọ́,*+ wọ́n á sì máa pe òkè Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ní òkè mímọ́.’”+
4 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ti darúgbó yóò pa dà jókòó ní àwọn ojúde ìlú Jerúsálẹ́mù, kálukú pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀ torí ọjọ́ ogbó wọn.*+ 5 Àwọn ojúde ìlú náà yóò sì kún fún àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tó ń ṣeré.’”+
6 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn yìí láwọn ọjọ́ yẹn lè máa wò ó bíi pé ó ṣòro gan-an, ṣé ó yẹ kó dà bíi pé ó ṣòro gan-an fún èmi náà?’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”
7 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Èmi yóò gba àwọn èèyàn mi là láti àwọn ilẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn.*+ 8 Èmi yóò mú wọn wá, wọn yóò sì máa gbé ní Jerúsálẹ́mù;+ wọn yóò di èèyàn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn+ ní òtítọ́ àti ní òdodo.’”
9 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ẹ jẹ́ onígboyà,*+ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí láti ẹnu àwọn wòlíì,+ ọ̀rọ̀ yìí náà ni wọ́n sọ ní ọjọ́ tí wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun lélẹ̀ kí wọ́n lè kọ́ tẹ́ńpìlì náà. 10 Torí ṣáájú ìgbà yẹn, wọn kì í san owó iṣẹ́ fún èèyàn tàbí ẹranko;+ àwọn èèyàn ò lè lọ kí wọ́n sì bọ̀ láìséwu torí ọ̀tá, torí mo ti kẹ̀yìn gbogbo èèyàn sí ara wọn.’
11 “‘Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, mi ò ní ṣe bíi ti àtijọ́ sí àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn yìí,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 12 Torí èso tí wọ́n máa gbìn yóò mú àlàáfíà wá; àjàrà yóò so èso, ilẹ̀ yóò mú èso rẹ̀ jáde,+ ọ̀run yóò sẹ ìrì; èmi yóò sì mú kí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn yìí jogún gbogbo nǹkan yìí.+ 13 Ẹ̀yin ilé Júdà àti ilé Ísírẹ́lì, bí ẹ ṣe di ẹni ègún láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ bẹ́ẹ̀ náà ni èmi yóò gbà yín là, ẹ ó sì di ẹni ìbùkún.+ Ẹ má bẹ̀rù!+ Ẹ jẹ́ onígboyà.’*+
14 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘“Bí mo ṣe pinnu láti mú àjálù wá sórí yín torí àwọn baba ńlá yín múnú bí mi, tí mi ò sì pèrò dà,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,+ 15 “bẹ́ẹ̀ náà ni mo ṣe pinnu báyìí láti ṣe dáadáa sí Jerúsálẹ́mù àti sí ilé Júdà.+ Ẹ má bẹ̀rù!”’+
16 “‘Àwọn ohun tó yẹ kí ẹ ṣe nìyí: Ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́,+ kí ẹ sì máa dá ẹjọ́ òtítọ́ àti ti àlàáfíà ní ẹnubodè yín.+ 17 Ẹ má gbèrò ibi sí ara yín nínú ọkàn yín,+ ẹ má sì fẹ́ràn ìbúra èké,+ torí mo kórìíra gbogbo àwọn nǹkan yìí,’+ ni Jèhófà wí.”
18 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 19 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ààwẹ̀ oṣù kẹrin,+ ààwẹ̀ oṣù karùn-ún,+ ààwẹ̀ oṣù keje+ àti ààwẹ̀ oṣù kẹwàá+ yóò di àsìkò ìdùnnú àti ayọ̀ fún ilé Júdà, yóò jẹ́ àjọ̀dún aláyọ̀.+ Torí náà, ẹ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.’
20 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Yóò ṣẹlẹ̀ pé àwọn èèyàn àti àwọn tó ń gbé ọ̀pọ̀ ìlú yóò wá; 21 àwọn tó ń gbé ìlú kan yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń gbé ìlú míì, wọ́n á sì sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká tètè lọ bẹ Jèhófà pé kó ṣojúure sí wa,* ká sì wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. Èmi náà yóò lọ.”+ 22 Ọ̀pọ̀ èèyàn àti orílẹ̀-èdè alágbára yóò wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ kí wọ́n sì lè bẹ Jèhófà pé kó ṣojúure sí àwọn.’*
23 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ní àwọn ọjọ́ yẹn, ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè+ yóò di aṣọ* Júù* kan mú, àní wọn yóò dì í mú ṣinṣin, wọ́n á sì sọ pé: “A fẹ́ bá yín lọ,+ torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”’”+
9 Ìkéde:
“Jèhófà bá ilẹ̀ Hádírákì wí,
Damásíkù gangan ni ọ̀rọ̀ náà kàn,*+
Torí ojú Jèhófà wà lára aráyé+
Àti lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
3 Tírè kọ́ odi ààbò* fún ara rẹ̀.
Ó to fàdákà jọ pelemọ bí iyẹ̀pẹ̀
Àti wúrà bí iyẹ̀pẹ̀ ojú ọ̀nà.+
4 Wò ó! Jèhófà máa gba àwọn ohun ìní rẹ̀,
Yóò sì run àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sínú òkun;*+
Iná yóò sì jẹ ẹ́ run.+
5 Áṣíkẹ́lónì á rí i, ẹ̀rù á sì bà á;
Gásà yóò jẹ̀rora,
Bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹ́kírónì, torí pé ìrètí rẹ̀ ti di ìtìjú.
Ọba kan yóò ṣègbé ní Gásà,
Ẹnì kankan kò sì ní gbé ní Áṣíkẹ́lónì.+
7 Èmi yóò mú àwọn ohun tí ẹ̀jẹ̀ ti yí kúrò ní ẹnu rẹ̀
Àti àwọn ohun ìríra kúrò láàárín eyín rẹ̀,
Àwọn tó ṣẹ́ kù níbẹ̀ yóò sì di ti Ọlọ́run wa;
Òun yóò dà bí séríkí* ní Júdà,+
Ẹ́kírónì yóò sì dà bí àwọn ará Jébúsì.+
8 Èmi yóò pàgọ́ bí ẹ̀ṣọ́* fún ilé mi,+
Kí ẹnì kankan má bàa gba ibẹ̀ kọjá tàbí pa dà wá;
Akóniṣiṣẹ́* kankan kò ní gba ibẹ̀ kọjá mọ́,+
Torí mo ti fi ojú mi rí i* báyìí.
9 Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.
Kígbe ìṣẹ́gun, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù.
Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.+
10 Èmi yóò mú kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí wọ́n fi ń jagun kúrò ní Éfúrémù
Àti ẹṣin kúrò ní Jerúsálẹ́mù.
Ọfà tí wọ́n fi ń jagun kò ní sí mọ́.
Òun yóò sì kéde àlàáfíà fún àwọn orílẹ̀-èdè;+
Yóò jọba láti òkun dé òkun
11 Ní ti ìwọ obìnrin, nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú rẹ,
Èmi yóò rán àwọn ẹlẹ́wọ̀n rẹ jáde kúrò nínú kòtò tí kò lómi.+
12 Ẹ pa dà síbi ààbò, ẹ̀yin ẹlẹ́wọ̀n tó ní ìrètí.+
Mò ń sọ fún ọ lónìí pé,
‘Ìwọ obìnrin, màá san án pa dà fún ọ ní ìlọ́po méjì.+
13 Torí èmi yóò fa* Júdà bí ọrun mi.
Màá fi Éfúrémù sínú ọrun* náà,
Màá sì jí àwọn ọmọ rẹ, ìwọ Síónì,
Láti dojú kọ àwọn ọmọ rẹ, ìwọ ilẹ̀ Gíríìsì,
Màá sì ṣe ọ́ bí idà jagunjagun.’
14 Ó máa hàn pé Jèhófà wà pẹ̀lú wọn,
Ọfà rẹ̀ á sì jáde lọ bíi mànàmáná.
Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò fun ìwo,+
Yóò sì gbéra pẹ̀lú ìjì líle ti gúúsù.
15 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun yóò gbèjà wọn,
Wọn yóò jẹ òkúta kànnàkànnà run, wọn yóò sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.+
Wọ́n á mu, wọ́n á sì pariwo bíi pé wọ́n mu wáìnì;
Wọn yóò kún bí abọ́ tí wọ́n fi ń rúbọ,
Bí àwọn igun pẹpẹ.+
16 Jèhófà Ọlọ́run wọn yóò gbà wọ́n là ní ọjọ́ yẹn,
Àwọn èèyàn rẹ̀, bí agbo àgùntàn;+
Torí wọn yóò dà bí òkúta iyebíye tó wà lára adé* tó ń dán yinrin lórí ilẹ̀ rẹ̀.+
17 Oore rẹ̀ mà pọ̀ o,+
Ó mà lẹ́wà gan-an o!
Ọkà yóò mú kí àwọn géńdé ọkùnrin lágbára,
Wáìnì tuntun yóò sì fún àwọn wúńdíá lókun.”+
10 “Ẹ bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí òjò rọ̀ ní àsìkò ìrúwé.
Àlá tí kò ní láárí ni wọ́n ń rọ́,
Lásán sì ni wọ́n ń gbìyànjú láti tu àwọn èèyàn nínú.
Ìdí nìyẹn tí wọ́n á fi rìn gbéregbère bí àgùntàn.
Wọ́n á jìyà torí kò sí olùṣọ́ àgùntàn.
3 Inú bí mi gan-an sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn,
Èmi yóò sì mú kí àwọn aṣáájú tó ń ni àwọn èèyàn lára* jíhìn;
Torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti yíjú sí agbo rẹ̀,+ sí ilé Júdà,
Ó sì mú kí wọ́n dà bí ẹṣin rẹ̀ tó gbayì tó fi ń jagun.
4 Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni olórí* ti wá,
Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni alákòóso tó ń tini lẹ́yìn* ti wá,
Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ọfà tí wọ́n fi ń jagun ti wá;
Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo alábòójútó,* ti jáde lọ, gbogbo wọn pátá.
5 Wọn yóò dà bí àwọn jagunjagun,
Tó ń tẹ ẹrọ̀fọ̀ ojú ọ̀nà mọ́lẹ̀ lójú ogun.
6 Èmi yóò gbé ilé Júdà lékè,
Èmi yóò sì gba ilé Jósẹ́fù là.+
Màá dá wọn pa dà,
Torí èmi yóò ṣàánú wọn;+
Wọn yóò sì dà bí ẹni tí mi ò ta nù rí;+
Torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn, màá sì dá wọn lóhùn.
7 Àwọn ti Éfúrémù yóò dà bíi jagunjagun tó lákíkanjú,
Ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bíi pé wọ́n mu wáìnì.+
Àwọn ọmọ wọn á rí èyí, inú wọn á sì dùn;
Ọkàn wọn máa yọ̀ torí Jèhófà.+
8 ‘Màá súfèé sí wọn, màá sì kó wọn jọ;
Torí màá rà wọ́n pa dà,+ wọ́n á sì pọ̀ sí i,
Wọ́n á sì máa pọ̀ sí i.
9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fọ́n wọn ká bí irúgbìn sáàárín àwọn èèyàn,
Wọ́n á rántí mi ní ọ̀nà jíjìn tí wọ́n wà;
Wọn á pa dà lókun, pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọ́n á sì pa dà.
10 Màá mú wọn pa dà wá láti ilẹ̀ Íjíbítì,
Màá sì kó wọn jọ láti Ásíríà;+
Màá mú wọn wá sí ilẹ̀ Gílíádì+ àti Lẹ́bánónì,
Kò sì ní sí àyè fún wọn.+
Ìgbéraga Ásíríà yóò rọlẹ̀,
Ọ̀pá àṣẹ Íjíbítì yóò sì kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+
11 “Ṣí àwọn ilẹ̀kùn rẹ, ìwọ Lẹ́bánónì,
Kí iná lè run àwọn igi kédárì rẹ.
2 Pohùn réré ẹkún, ìwọ igi júnípà, torí igi kédárì ti ṣubú;
Àwọn igi ńláńlá ti pa run!
Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin igi ràgàjì* ní Báṣánì,
Torí wọ́n ti gé igbó kìjikìji lulẹ̀!
3 Ẹ fetí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń pohùn réré ẹkún,
Torí ògo wọn ti wọmi.
Ẹ fetí sílẹ̀! Àwọn ọmọ kìnnìún* ń ké ramúramù,
Torí igbó tó wà lẹ́bàá Jọ́dánì ti pa run.
4 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run mi sọ nìyí, ‘Bójú tó agbo ẹran tí wọ́n fẹ́ pa,+ 5 àwọn tó ra àwọn ẹran náà pa wọ́n,+ wọn ò sì dá wọn lẹ́bi. Àwọn tó ń tà wọ́n+ sì sọ pé: “Ẹ yin Jèhófà, torí màá di ọlọ́rọ̀.” Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ò sì káàánú wọn.’+
6 “Jèhófà sọ pé, ‘Mi ò ní káàánú àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà mọ́. Torí náà, màá mú kí kálukú kó sí ọwọ́ ọmọnìkejì rẹ̀ àti sí ọwọ́ ọba rẹ̀; wọ́n á pa ilẹ̀ náà run, mi ò sì ní gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ wọn.’”
7 Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó agbo ẹran tí wọ́n fẹ́ pa,+ ẹ̀yin tí ìyà ń jẹ nínú agbo ẹran ni mo sì ṣe é fún. Torí náà, mo mú ọ̀pá méjì, mo pe ọ̀kan ní Adùn, mo sì pe èkejì ní Ìṣọ̀kan,+ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran. 8 Ní oṣù kan, mo lé olùṣọ́ àgùntàn mẹ́ta kúrò lẹ́nu iṣẹ́, torí ọ̀rọ̀ wọn sú mi,* àwọn* pẹ̀lú sì kórìíra mi. 9 Mo sì sọ pé: “Mi ò ní ṣe olùṣọ́ àgùntàn yín mọ́. Kí ẹni tó ń kú lọ kú, kí ẹni tó ń ṣègbé lọ sì ṣègbé. Ní ti àwọn tó ṣẹ́ kù, kí wọ́n jẹ ẹran ara wọn.” 10 Torí náà, mo mú ọ̀pá mi tó ń jẹ́ Adùn,+ mo sì kán an, mo sì fagi lé májẹ̀mú mi tí mo bá gbogbo àwọn èèyàn náà dá. 11 Mo fagi lé e lọ́jọ́ yẹn, àwọn tí ìyà ń jẹ nínú agbo ẹran tó ń wò mí sì mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ni.
12 Ni mo bá sọ fún wọn pé: “Tó bá dára lójú yín, ẹ fún mi ní owó iṣẹ́; tí kò bá sì dára lójú yín, ẹ mú un dání.” Wọ́n sì san* owó iṣẹ́ mi, ó jẹ́ ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà.+
13 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Sọ owó náà sí ibi ìṣúra, iye tó jọjú tí wọ́n rò pé ó tọ́ sí mi.”+ Torí náà, mo mú ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà náà, mo sì sọ ọ́ sí ibi ìṣúra ní ilé Jèhófà.+
14 Lẹ́yìn náà, mo kán ọ̀pá mi kejì tó ń jẹ́ Ìṣọ̀kan,+ mo sì ba àjọṣe tó wà láàárín Júdà àti Ísírẹ́lì jẹ́.+
15 Jèhófà sì sọ fún mi pé: “Ó yá, lọ sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn kan tí kò wúlò, kí o sì mú irinṣẹ́ rẹ̀.+ 16 Torí èmi yóò gbé olùṣọ́ àgùntàn kan dìde ní ilẹ̀ náà. Kò ní tọ́jú àwọn àgùntàn tó ń ṣègbé lọ;+ kò ní wá àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn, kò ní tọ́jú àwọn tó fara pa,+ kò sì ní bọ́ àwọn tó lókun láti dúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, á jẹ ẹran ara àwọn tó sanra,+ á sì ya pátákò àwọn àgùntàn.+
17 O gbé, ìwọ olùṣọ́ àgùntàn mi tí kò wúlò,+ tó ń pa agbo ẹran tì!+
Idà yóò ṣá a ní apá àti ojú ọ̀tún rẹ̀.
Apá rẹ̀ á rọ pátápátá,
Ojú ọ̀tún rẹ̀ á sì fọ́ yán-án yán-án.”*
12 Ìkéde:
“Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Ísírẹ́lì,”
2 “Èmi yóò sọ Jerúsálẹ́mù di ife* tó ń mú kí gbogbo àwọn tó yí i ká ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́; wọn yóò sì gbógun ti Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+ 3 Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò sọ Jerúsálẹ́mù di òkúta tó wúwo* fún gbogbo èèyàn. Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá gbé e máa fara pa yánnayànna;+ gbogbo orílẹ̀-èdè ayé sì máa kóra jọ láti gbéjà kò ó.+ 4 Jèhófà sọ pé, “Ní ọjọ́ yẹn, màá dẹ́rù ba gbogbo ẹṣin, màá sì mú kí orí ẹni tó ń gùn ún dà rú. Ojú mi yóò wà lára ilé Júdà, àmọ́ màá fọ́ ojú gbogbo ẹṣin àwọn èèyàn náà. 5 Àwọn séríkí* Júdà yóò sì sọ nínú ọkàn wọn pé, ‘Àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ti fún wa lókun nípasẹ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọlọ́run wọn.’+ 6 Ní ọjọ́ yẹn, màá ṣe àwọn séríkí Júdà bí ìkòkò iná láàárín igi àti bí ògùṣọ̀ oníná láàárín ìtí ọkà+ tí wọ́n tò jọ, wọn yóò sì jó gbogbo èèyàn tó wà yí ká run ní ọ̀tún àti ní òsì;+ àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù yóò sì pa dà sí àyè wọn,* ní Jerúsálẹ́mù.+
7 “Jèhófà yóò kọ́kọ́ gba àgọ́ Júdà là, kí iyì* ilé Dáfídì àti iyì* àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù má bàa pọ̀ gan-an ju ti Júdà lọ. 8 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù;+ ní ọjọ́ yẹn, ẹni tó bá kọsẹ̀* nínú wọn yóò dà bíi Dáfídì, ilé Dáfídì yóò sì dà bí Ọlọ́run, bí áńgẹ́lì Jèhófà tó ń lọ níwájú wọn.+ 9 Ní ọjọ́ yẹn, ó dájú pé màá pa gbogbo orílẹ̀-èdè tó wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù run.+
10 “Màá tú ẹ̀mí ojú rere àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dáfídì àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, wọ́n máa wo ẹni tí wọ́n gún,+ wọ́n sì máa pohùn réré ẹkún torí rẹ̀ bí ìgbà tí wọ́n ń sunkún torí ọmọkùnrin kan ṣoṣo; wọ́n sì máa ṣọ̀fọ̀ gan-an torí rẹ̀ bí ìgbà tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ torí àkọ́bí ọmọkùnrin. 11 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n á pohùn réré ẹkún gan-an ní Jerúsálẹ́mù, bí ẹkún tí wọ́n sun ní Hadadirímónì ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mẹ́gídò.+ 12 Ilẹ̀ náà máa pohùn réré ẹkún, ìdílé kọ̀ọ̀kan lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dáfídì lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; ìdílé Nátánì+ lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; 13 ìdílé Léfì+ lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; ìdílé àwọn ọmọ Ṣíméì+ lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; 14 àti gbogbo ìdílé tó ṣẹ́ kù, ìdílé kọ̀ọ̀kan lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.
13 “Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò gbẹ́ kànga kan fún ilé Dáfídì àti fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ àti èérí wọn mọ́.+
2 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò pa orúkọ àwọn òrìṣà rẹ́ ní ilẹ̀ náà,+ wọn ò sì ní rántí wọn mọ́; èmi yóò sì mú àwọn wòlíì+ àti ẹ̀mí àìmọ́ kúrò ní ilẹ̀ náà. 3 Tí ọkùnrin kan bá tún ń sọ tẹ́lẹ̀, bàbá àti ìyá tó bí i yóò sọ fún un pé, ‘O ti fi orúkọ Jèhófà parọ́, o máa kú ni!’ Bàbá àti ìyá tó bí i yóò sì gún un pa torí pé ó sọ àsọtẹ́lẹ̀.+
4 “Ní ọjọ́ yẹn, ojú yóò ti àwọn wòlíì nítorí ìran tí kálukú wọn ń rí nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀; wọn ò sì ní wọ aṣọ onírun+ mọ́ láti tan àwọn èèyàn jẹ. 5 Yóò sì sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe wòlíì. Àgbẹ̀ ni mí, torí ọkùnrin kan rà mí láti kékeré.’ 6 Tí ẹnì kan bá sì bi í pé, ‘Ọgbẹ́ wo ló wà lára rẹ yìí?’* yóò dáhùn pé, ‘Ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi* ni mo ti fara gba ọgbẹ́.’”
7 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ìwọ idà, dìde sí olùṣọ́ àgùntàn mi,+
Sí ọkùnrin tó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi.
Kọ lu olùṣọ́ àgùntàn,+ kí agbo* sì tú ká;+
Èmi yóò sì yí ọwọ́ mi pa dà sí àwọn tí kò já mọ́ nǹkan kan.”
8 Jèhófà sọ pé, “Ní gbogbo ilẹ̀ náà,
Ìdá méjì nínú rẹ̀ yóò pa run, yóò sì ṣègbé;*
Ìdá kẹta yóò sì ṣẹ́ kù síbẹ̀.
9 Èmi yóò fi ìdá kẹta sínú iná;
Èmi yóò yọ́ wọn mọ́ bí wọ́n ṣe ń yọ́ fàdákà mọ́,
Èmi yóò sì yẹ̀ wọ́n wò bí wọ́n ṣe ń yẹ wúrà wò.+
Wọ́n á ké pe orúkọ mi,
Èmi yóò sì dá wọn lóhùn.
Màá sọ pé, ‘Èèyàn mi ni wọ́n,’+
Wọ́n á sì sọ pé, ‘Jèhófà ni Ọlọ́run wa.’”
14 “Wò ó! Ọjọ́ náà ń bọ̀. Ti Jèhófà ni ọjọ́ náà, àárín yín ni wọn yóò ti pín ẹrù yín* tí wọ́n kó ní ọjọ́ náà. 2 Màá kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ láti gbógun ti Jerúsálẹ́mù; wọ́n á gba ìlú náà, wọ́n á kó ẹrù nínú àwọn ilé, wọ́n á sì fipá bá àwọn obìnrin lò pọ̀. Ìdajì ìlú náà á sì lọ sí ìgbèkùn, àmọ́ wọn ò ní kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn náà kúrò ní ìlú náà.
3 “Jèhófà yóò jáde lọ gbéjà ko àwọn orílẹ̀-èdè+ yẹn bí ìgbà tó ń jà ní ọjọ́ ogun.+ 4 Ní ọjọ́ yẹn, ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò dúró sórí Òkè Ólífì,+ tó dojú kọ Jerúsálẹ́mù ní ìlà oòrùn; Òkè Ólífì yóò là sí méjì láti ìlà oòrùn* dé ìwọ̀ oòrùn,* àfonífojì ńlá kan yóò sì wà láàárín rẹ̀; ìdajì òkè náà yóò sún sí àríwá àti ìdajì sí gúúsù. 5 Ẹ máa sá lọ sí àfonífojì àárín àwọn òkè mi; torí àfonífojì àárín àwọn òkè náà yóò dé Ásélì lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún. Ẹ máa sá lọ, bí ẹ ṣe sá lọ torí ìmìtìtì ilẹ̀ láyé ìgbà Ùsáyà ọba Júdà.+ Jèhófà Ọlọ́run mi yóò wá, gbogbo àwọn ẹni mímọ́ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+
6 “Ní ọjọ́ yẹn, kò ní sí ìmọ́lẹ̀ tó tàn yòò;+ àwọn nǹkan yóò dì.* 7 Yóò sì di ọjọ́ kan tí a mọ̀ sí ti Jèhófà.+ Kò ní jẹ́ ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni kò ní jẹ́ òru; ìmọ́lẹ̀ yóò sì wà ní ìrọ̀lẹ́. 8 Ní ọjọ́ yẹn, omi ìyè+ yóò ṣàn jáde láti Jerúsálẹ́mù,+ ìdajì rẹ̀ sí ọ̀nà òkun ìlà oòrùn*+ àti ìdajì rẹ̀ sí ọ̀nà òkun ìwọ̀ oòrùn.*+ Yóò ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ní ìgbà òtútù. 9 Jèhófà yóò sì jẹ́ Ọba lórí gbogbo ayé.+ Jèhófà yóò jẹ́ ọ̀kan ní ọjọ́ yẹn,+ orúkọ rẹ̀ yóò sì jẹ́ ọ̀kan.+
10 “Gbogbo ilẹ̀ náà láti Gébà+ dé Rímónì+ ní gúúsù Jerúsálẹ́mù yóò dà bí Árábà;+ yóò dìde, yóò sì máa gbé àyè rẹ̀,+ láti Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì+ títí lọ dé ibi Ẹnubodè Àkọ́kọ́, títí lọ dé Ẹnubodè Igun àti láti Ilé Gogoro Hánánélì+ títí lọ dé àwọn ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì* tó jẹ́ ti ọba. 11 Àwọn èèyàn yóò gbé inú rẹ̀; kò tún ní sí ìparun tí ègún fà mọ́,+ wọn yóò sì máa gbé Jerúsálẹ́mù ní àlàáfíà.+
12 “Èyí ni àjàkálẹ̀ àrùn tí Jèhófà yóò fi kọ lu gbogbo èèyàn tó bá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù:+ Ẹran ara wọn yóò jẹrà lórí ìdúró, ojú wọn yóò jẹrà ní agbárí wọn, ahọ́n wọn yóò sì jẹrà ní ẹnu wọn.
13 “Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà yóò da àárín wọn rú; kálukú wọn yóò gbá ọwọ́ ẹnì kejì rẹ̀ mú, wọn yóò sì gbéjà ko ara wọn.*+ 14 Júdà pẹ̀lú yóò jagun ní Jerúsálẹ́mù; ọrọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ni wọ́n á sì kó jọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà àti fàdákà àti aṣọ.+
15 “Irú àjàkálẹ̀ àrùn yẹn yóò tún kọ lu àwọn ẹṣin, ìbaaka, ràkúnmí, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti gbogbo ẹran ọ̀sìn tó wà nínú àwọn àgọ́ yẹn.
16 “Gbogbo ẹni tó ṣẹ́ kù nínú gbogbo orílẹ̀-èdè tó wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù yóò máa lọ láti ọdún dé ọdún+ kí wọ́n lè tẹrí ba fún* Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọba,+ kí wọ́n sì lè ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà.+ 17 Àmọ́ tí ẹnì kankan nínú àwọn ìdílé tó wà ní ayé kò bá lọ sí Jerúsálẹ́mù láti tẹrí ba fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọba, òjò kò ní rọ̀ sórí wọn.+ 18 Tí ìdílé àwọn ará Íjíbítì kò bá wá, tí wọn ò sì wọlé wá, òjò kò ní rọ̀ sórí wọn. Dípò ìyẹn, àjàkálẹ̀ àrùn tí Jèhófà fi kọ lu àwọn orílẹ̀-èdè tí kò wá ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà ni yóò kọ lù wọ́n. 19 Èyí ni yóò jẹ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ Íjíbítì àti ìyà ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò wá ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà.
20 “Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò kọ ọ̀rọ̀ náà, ‘Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà!’+ sára àwọn agogo tí wọ́n so mọ́ àwọn ẹṣin. Àwọn ìkòkò oúnjẹ*+ inú ilé Jèhófà yóò sì dà bí àwọn abọ́+ níwájú pẹpẹ. 21 Gbogbo ìkòkò oúnjẹ* ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà yóò di mímọ́, yóò sì jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, gbogbo àwọn tó ń rúbọ yóò wọlé wá, wọn yóò sì lò lára rẹ̀ láti fi se nǹkan. Ní ọjọ́ yẹn, kò ní sí ọmọ Kénáánì* kankan mọ́ nínú ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.”+
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Rántí.”
Tàbí “ẹ pa dà nínú ìwà búburú.”
Wo Àfikún B15.
Ìyẹn, ìlú tí kò ní odi.
Ní Héb., “sí afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.”
Tàbí “ojú.”
Tàbí “ẹran ara.”
Tàbí “ẹ̀bi.”
Tàbí “aṣọ ìgúnwà.”
Tàbí “tọ́jú; ṣọ́.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “ọjọ́ àwọn ohun kékeré?”
Ní Héb., “òkúta, tánganran.”
Ìyẹn, ẹ̀ka igi tó so èso wọ̀ǹtìwọnti.
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ ṣẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “eéfà,” nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí ohun ìkó-nǹkan-sí tàbí apẹ̀rẹ̀ tó dọ́gba pẹ̀lú òṣùwọ̀n eéfà. Eéfà kan jẹ́ Lítà 22. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “Wọ́n sì gbé agbọ̀n náà sí àárín ayé àti ọ̀run.”
Ìyẹn, Babilóníà.
Ìyẹn, kẹ̀kẹ́ ẹṣin.
Tàbí “adé ńlá.”
Ìyẹn, ipò rẹ̀ bí alákòóso àti àlùfáà.
Tàbí “Adé ńlá.”
Wo Àfikún B15.
Tàbí “tu Jèhófà lójú.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “ọmọ aláìlóbìí.”
Tàbí kó jẹ́, “òkúta líle,” irú bí òkúta émérì.
Tàbí “ìtọ́ni.”
Ní Héb., “ó.”
Tàbí “òdodo.”
Ní Héb., “wọ́n ti lọ́jọ́ lórí.”
Tàbí “láti ilẹ̀ yíyọ oòrùn àti láti ilẹ̀ wíwọ̀ oòrùn.”
Tàbí “Ẹ fún ọwọ́ yín lókun.”
Tàbí “Ẹ fún ọwọ́ yín lókun.”
Tàbí “tu Jèhófà lójú.”
Tàbí “tu Jèhófà lójú.”
Tàbí “etí aṣọ.”
Ní Héb., “ọkùnrin Júù kan.”
Ní Héb., “ni ibi ìsinmi rẹ̀.”
Tàbí “ilé ààbò.”
Tàbí kó jẹ́, “lórí òkun.”
Séríkí jẹ́ olóyè láàárín ẹ̀yà kan.
Tàbí “ọmọ ogun ẹ̀yìn odi.”
Tàbí “aninilára.”
Ó ṣe kedere pé, ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ ló ń sọ.
Tàbí “ó sì ń ṣẹ́gun; ó sì gbani là.”
Tàbí “akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
Ìyẹn, odò Yúfírétì.
Ní Héb., “tẹ.”
Ìyẹn, bí ọfà.
Tàbí “dáyádémà.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; àwọn òrìṣà.”
Tàbí “sọ ohun abàmì; sọ ohun àdììtú.”
Ní Héb., “òbúkọ.”
Ní Héb., “ilé ìṣọ́ igun ilé,” ó ṣàpẹẹrẹ èèyàn pàtàkì; ìjòyè.
Ní Héb., “èèkàn,” ó ṣàpẹẹrẹ ẹni tó ń tini lẹ́yìn; alákòóso.
Tàbí “akóniṣiṣẹ́.”
Tàbí “igi óákù.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ọkàn wọn.”
Ní Héb., “díwọ̀n.”
Ní Héb., “di bàìbàì.”
Tàbí “èémí.”
Tàbí “abọ́.”
Tàbí “òkúta tó jẹ́ ẹrù ìnira.”
Séríkí jẹ́ olóyè láàárín ẹ̀yà kan.
Tàbí “àyè tó tọ́ sí wọn.”
Tàbí “ẹwà.”
Tàbí “ẹwà.”
Tàbí “ẹni tó jẹ́ aláìlera jù lọ.”
Ní Héb., “láàárín ọwọ́ rẹ yìí?” Ìyẹn, ní àyà tàbí ẹ̀yìn.
Tàbí “àwọn tó fẹ́ràn mi.”
Tàbí “àgùntàn.”
Tàbí “kú.”
Ìyẹn, ìlú tó wà nínú ẹsẹ 2.
Tàbí “yíyọ oòrùn.”
Ní Héb., “òkun.”
Tàbí “dúró gbagidi,” bíi pé òtútù mú kó gan.
Ìyẹn, Òkun Òkú.
Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.
Tàbí “dé ẹkù ìfúntí.”
Tàbí “ọwọ́ rẹ̀ yóò sì gbéjà ko ọwọ́ ẹnì kejì rẹ̀.”
Tàbí “jọ́sìn.”
Tàbí “ìkòkò ìsebẹ̀ ẹlẹ́nu fífẹ̀.”
Tàbí “ìkòkò ìsebẹ̀ ẹlẹ́nu fífẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “oníṣòwò.”