JÓẸ́LÌ
1 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jóẹ́lì* ọmọ Pétúélì sọ nìyí:
Ǹjẹ́ irú nǹkan báyìí ti ṣẹlẹ̀ rí níṣojú yín,
Tàbí nígbà ayé àwọn baba ńlá yín?+
3 Ẹ sọ nípa rẹ̀ fún àwọn ọmọ yín,
Kí àwọn ọmọ yín náà sọ fún àwọn ọmọ wọn,
Kí àwọn ọmọ wọn sì sọ fún ìran tó tẹ̀ lé wọn.
4 Ohun tí eéṣú tó ń jẹ nǹkan run jẹ kù, ni ọ̀wọ́ eéṣú jẹ;+
Ohun tí ọ̀wọ́ eéṣú jẹ kù, ni eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́ jẹ;
Ohun tí eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́ jẹ kù, ni ọ̀yánnú eéṣú jẹ.+
5 Ẹ jí, ẹ̀yin ọ̀mùtípara,+ kí ẹ sì sunkún!
Ẹ pohùn réré ẹkún, gbogbo ẹ̀yin tó ń mu wáìnì,
Torí wọ́n ti gba wáìnì dídùn lẹ́nu yín.+
6 Torí orílẹ̀-èdè kan ti gòkè wá sí ilẹ̀ mi, ó lágbára gan-an, kò sì lóǹkà.+
Eyín kìnnìún ni eyín rẹ̀,+ páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ náà sì jẹ́ ti kìnnìún.
7 Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì sọ igi ọ̀pọ̀tọ́ mi di kùkùté,
Ó bó èèpo wọn kanlẹ̀, ó sì jù wọ́n dà nù,
Ẹ̀ka àwọn igi náà sì di funfun.
10 Wọ́n ti pa oko run, ilẹ̀ sì ń ṣọ̀fọ̀;+
Wọ́n ti run ọkà, wáìnì tuntun ti gbẹ táútáú, òróró sì ti tán.+
11 Inú àwọn àgbẹ̀ bà jẹ́, àwọn tó ń rẹ́wọ́ àjàrà pohùn réré ẹkún,
Torí àlìkámà* àti ọkà bálì;
Ìkórè oko sì ti pa run.
12 Àjàrà ti gbẹ,
Igi ọ̀pọ̀tọ́ sì ti kú.
Bẹ́ẹ̀ náà ni igi pómégíránétì, igi ọ̀pẹ àti igi ápù,
Gbogbo igi oko ti gbẹ dà nù;+
Ìdùnnú àwọn èèyàn ti di ìtìjú.
Ẹ wọlé, kí ẹ sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́jú, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi;
Torí àwọn èèyàn ò mú ọrẹ ọkà+ àti ọrẹ ohun mímu+ wá sílé Ọlọ́run yín.
14 Ẹ kéde* ààwẹ̀; ẹ pe àpéjọ ọlọ́wọ̀.+
Ẹ kó àwọn àgbààgbà àti gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jọ,
Sí ilé Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ sì ké pe Jèhófà pé kó ràn yín lọ́wọ́.
16 Wọ́n ti gbé oúnjẹ kúrò níwájú wa,
Kò sì sí ayọ̀ àti ìdùnnú nílé Ọlọ́run wa mọ́.
17 Àwọn èso* ti bà jẹ́ kí wọ́n tó fi ṣọ́bìrì kó o.
Àwọn ilé ìkẹ́rùsí ti di ahoro.
Wọ́n ti ya àwọn ibi tí wọ́n ń tọ́jú ọkà sí lulẹ̀, torí ọkà ti gbẹ dà nù.
18 Kódà, àwọn ẹran ọ̀sìn ń kérora!
Ìdààmú bá àwọn agbo màlúù, wọ́n sì ń rìn gbéregbère torí wọn ò rí ewéko jẹ.
Àwọn agbo àgùntàn sì jẹ nínú ìyà náà.
Torí iná ti run àwọn ibi ìjẹko nínú aginjù,
Ọwọ́ iná sì ti jẹ gbogbo igi oko run.
20 Kódà, àwọn ẹran inú igbó ń wá ọ,
Torí àwọn odò tó ń ṣàn ti gbẹ,
Iná sì ti run àwọn ibi ìjẹko nínú aginjù.”
2 “Ẹ fun ìwo ní Síónì!+
Ẹ kéde ogun ní òkè mímọ́ mi.
2 Ó jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,+
Ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà,+
Bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀ lórí àwọn òkè.
Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì lágbára;+
Kò tíì sí irú wọn rí,
Irú wọn kò sì ní sí mọ́ láé,
Jálẹ̀ àwọn ọdún láti ìran dé ìran.
3 Iná ń jẹ àwọn ohun tó wà níwájú wọn,
Ọwọ́ iná sì ń run àwọn ohun tó wà lẹ́yìn wọn.+
Ilẹ̀ iwájú wọn dà bí ọgbà Édẹ́nì,+
Àmọ́ aginjù tó ti di ahoro ló wà lẹ́yìn wọn,
Kò sì sí ohun tó lè yè bọ́.
4 Wọ́n rí bí ẹṣin,
Wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin ogun.+
5 Ìró wọn dà bíi ti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó ń bẹ́ gìjà lórí àwọn òkè,+
Bí ìró iná ajófòfò tó ń jó àgékù pòròpórò.
Wọ́n dà bí àwọn alágbára, tí wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun.+
6 Ìdààmú máa bá àwọn èèyàn náà nítorí wọn,
Ìbẹ̀rù yóò sì hàn lójú gbogbo èèyàn.
7 Wọ́n ń rọ́ gììrì bí àwọn jagunjagun,
Wọ́n gun ògiri bí àwọn ọmọ ogun,
Wọ́n tò tẹ̀ léra,
Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò sì kúrò lójú ọ̀nà rẹ̀.
8 Wọn kì í ti ara wọn;
Kálukú wọn ń tọ ọ̀nà tirẹ̀.
Bí ohun ìjà* bá gbé àwọn kan ṣubú lára wọn,
Àwọn tó ṣẹ́ kù kì í tú ká.
9 Wọ́n rọ́ wọnú ìlú, wọ́n sáré lórí ògiri.
Wọ́n gun orí àwọn ilé, wọ́n sì gba àwọn ojú fèrèsé* wọlé bí olè.
10 Ilẹ̀ mì tìtì níwájú wọn, ọ̀run sì mì jìgìjìgì.
Oòrùn àti òṣùpá ti ṣókùnkùn,+
Àwọn ìràwọ̀ kò sì mọ́lẹ̀ mọ́.
11 Jèhófà yóò gbé ohùn sókè níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀,+ torí wọ́n pọ̀ gan-an nínú ibùdó rẹ̀.+
Alágbára ni ẹni tó ń mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ;
Torí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jèhófà, ó sì ń bani lẹ́rù.+
Ta ló lè fara dà á?”+
12 “Síbẹ̀, ẹ fi gbogbo ọkàn yín pa dà sọ́dọ̀ mi báyìí,” ni Jèhófà wí,+
“Kí ẹ gbààwẹ̀,+ kí ẹ sunkún, kí ẹ sì pohùn réré ẹkún.
13 Ọkàn yín ni kí ẹ fà ya,+ kì í ṣe ẹ̀wù yín,+
Kí ẹ sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín,
Torí ó ń gba tẹni rò,* ó jẹ́ aláàánú, kì í tètè bínú,+ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,+
Òun yóò sì pèrò dà* nípa àjálù náà.
14 Ta ló mọ̀ bóyá ó máa tún ìpinnu ṣe, kó sì pèrò dà,*+
Kó sì mú kí ìbùkún ṣẹ́ kù fún yín,
Kí ẹ lè fi ọrẹ ọkà àti ọrẹ ohun mímu fún Jèhófà Ọlọ́run yín?
15 Ẹ fun ìwo ní Síónì!
Ẹ kéde ààwẹ̀;* ẹ pe àpéjọ ọlọ́wọ̀.+
16 Ẹ kó àwọn èèyàn náà jọ; ẹ sọ ìjọ di mímọ́.+
Ẹ kó àwọn àgbà ọkùnrin* jọ, kí ẹ sì kó àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọwọ́ jọ.+
Kí ọkọ ìyàwó jáde kúrò nínú yàrá rẹ̀ tó wà ní inú, kí ìyàwó pẹ̀lú kúrò nínú yàrá* rẹ̀.
‘Jèhófà, jọ̀ọ́ ṣàánú àwọn èèyàn rẹ;
Má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn fi ogún rẹ ṣẹlẹ́yà,
Kó wá di pé àwọn orílẹ̀-èdè á máa jọba lórí wọn,
Tí àwọn èèyàn á fi máa sọ pé, “Ibo ni Ọlọ́run wọn wà?”’+
19 Jèhófà yóò dá àwọn èèyàn rẹ̀ lóhùn pé:
‘Màá fi ọkà àti wáìnì tuntun àti òróró ránṣẹ́ sí yín,
Yóò sì tẹ́ yín lọ́rùn;+
Mi ò ní jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè fi yín ṣẹlẹ́yà mọ́.+
20 Màá lé àwọn ará àríwá jìnnà sí yín;
Màá fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ tí kò lómi tó sì ti di ahoro,
Àwọn tó wà níwájú yóò forí lé ọ̀nà òkun* ìlà oòrùn*
Àwọn tó wà lẹ́yìn yóò sì forí lé ọ̀nà òkun ìwọ̀ oòrùn.*
21 Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀.
Máa yọ̀, kí inú rẹ sì dùn, torí pé Jèhófà máa ṣe àwọn ohun ńlá.
22 Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹran inú igbó,
Torí àwọn ibi ìjẹko inú aginjù yóò hu ewéko tútù,+
Àwọn igi yóò sì mú èso jáde;+
Igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi àjàrà yóò so wọ̀ǹtìwọnti.+
23 Ẹ̀yin ọmọ Síónì, ẹ máa yọ̀, kí Jèhófà Ọlọ́run yín sì mú inú yín dùn;+
Torí ó máa rọ òjò fún yín ní ìwọ̀n tó yẹ nígbà ìwọ́wé,
Yóò sì rọ òjò lé yín lórí,
Nígbà ìwọ́wé àti nígbà ìrúwé, bíi ti tẹ́lẹ̀.+
24 Ọkà tó mọ́ máa kún àwọn ibi ìpakà,
Wáìnì tuntun àti òróró á sì kún àwọn ibi ìfúntí yín ní àkúnwọ́sílẹ̀.+
25 Màá sì san àwọn ohun tí ẹ ti pàdánù láwọn ọdún yẹn fún yín
Àwọn ọdún tí ọ̀wọ́ eéṣú, eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́, ọ̀yánnú eéṣú àti eéṣú tó ń jẹ nǹkan run fi jẹ irè oko yín,
Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán sáàárín yín.+
26 Ó dájú pé ẹ ó jẹ àjẹyó,+
Ẹ ó sì yin orúkọ Jèhófà Ọlọ́run yín,+
Ẹni tó ti ṣe ohun ìyanu fún yín;
Wọn ò ní dójú ti àwọn èèyàn mi mọ́ láé.+
Wọn ò ní dójú ti àwọn èèyàn mi mọ́ láé.
28 Lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò tú ẹ̀mí mi + sára onírúurú èèyàn,
Àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀,
Àwọn àgbà ọkùnrin yín yóò máa lá àlá.
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín yóò sì máa rí ìran.+
29 Kódà, ní àwọn ọjọ́ náà,
Èmi yóò tú ẹ̀mí mi sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi.
32 Gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà yóò sì rí ìgbàlà;+
Torí àwọn tó sá àsálà yóò wà ní Òkè Síónì àti ní Jerúsálẹ́mù+ bí Jèhófà ṣe sọ,
Àwọn tó là á já tí Jèhófà pè.”
3 “Wò ó! ní àwọn ọjọ́ náà àti ní àkókò yẹn,
Nígbà tí mo bá dá àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú láti Júdà àti Jerúsálẹ́mù pa dà,+
2 Èmi yóò tún kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ,
Èmi yóò dá wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀+
Nítorí àwọn èèyàn mi àti torí Ísírẹ́lì ogún mi,
Wọ́n ti tú wọn ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè,
Wọ́n sì ti pín ilẹ̀ mi láàárín ara wọn.+
3 Wọ́n ń ṣẹ́ kèké torí àwọn èèyàn mi;+
Wọ́n ń fi ọmọ wọn ọkùnrin dúró kí wọ́n lè gbé aṣẹ́wó,
Wọ́n sì ń ta àwọn ọmọ wọn obìnrin torí àtimu wáìnì.
4 Kí ló dé tí ẹ fi ṣe báyìí sí mi,
Tírè, Sídónì àti gbogbo ilẹ̀ Filísíà?
Ṣé mo ṣẹ̀ yín ni tí ẹ fi ń gbẹ̀san?
Tó bá jẹ́ ẹ̀san lẹ̀ ń gbà,
Ṣe ni màá yára dá a pa dà sórí yín láìjáfara.+
5 Torí ẹ ti kó fàdákà àti wúrà mi,+
Ẹ sì ti kó àwọn ìṣúra mi tó ṣeyebíye gan-an lọ sínú àwọn tẹ́ńpìlì yín;
6 Ẹ ti ta àwọn èèyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù fún àwọn Gíríìkì,+
Kí ẹ lè lé wọn jìnnà kúrò ní ilẹ̀ wọn;
7 Màá mú kí wọ́n pa dà láti ibi tí ẹ tà wọ́n sí,+
Màá sì dá ohun tí ẹ ṣe pa dà sórí yín.
8 Èmi yóò ta àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin fún àwọn ará Júdà,+
Wọn yóò sì tà wọ́n fún àwọn ará Ṣébà, orílẹ̀-èdè tó jìnnà réré;
Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́.
9 Ẹ kéde láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé:+
‘Ẹ múra ogun!* Ẹ ta àwọn alágbára ọkùnrin jí!
Kí gbogbo ọmọ ogun sún mọ́ tòsí, kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ogun!+
10 Ẹ fi àwọn ohun ìtúlẹ̀ yín rọ idà, kí ẹ sì fi àwọn ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn yín rọ ọ̀kọ̀.*
Kí ẹni tí kò lágbára sọ pé: “Alágbára ni mí.”
11 Ẹ wá ṣèrànwọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tó wà yí ká, kí ẹ sì kóra jọ!’”+
Jèhófà, jọ̀ọ́ mú àwọn jagunjagun* rẹ wá síbẹ̀.
12 “Kí àwọn orílẹ̀-èdè dìde, kí wọ́n sì wá sí Àfonífojì* Jèhóṣáfátì;
Torí ibẹ̀ ni èmi yóò jókòó sí láti dá gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà yí ká lẹ́jọ́.+
13 Ẹ ti dòjé bọ̀ ọ́, torí àkókò ìkórè ti tó.
Ẹ sọ̀ kalẹ̀ wá tẹ èso àjàrà, torí ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì ti kún.+
Àwọn ẹkù ti kún àkúnwọ́sílẹ̀, torí ìwà búburú kún ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.
15 Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn,
Àwọn ìràwọ̀ kò sì ní mọ́lẹ̀.
16 Jèhófà yóò sì fi ohùn rara sọ̀rọ̀ láti Síónì,
Yóò gbé ohùn rẹ̀ sókè láti Jerúsálẹ́mù.
Ọ̀run àti ayé yóò sì mì jìgìjìgì;
Àmọ́ Jèhófà yóò jẹ́ ibi ààbò fún àwọn èèyàn rẹ̀,+
Odi ààbò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
17 Ẹ ó sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, tó ń gbé ní Síónì, òkè mímọ́ mi.+
18 Wáìnì dídùn yóò máa sẹ̀ láti orí àwọn òkè ní ọjọ́ yẹn,+
Wàrà yóò máa ṣàn lórí àwọn òkè kéékèèké,
Gbogbo omi odò Júdà yóò sì máa ṣàn.
Omi yóò sun láti ilé Jèhófà,+
Yóò sì bomi rin Àfonífojì Àwọn Igi Bọn-ọ̀n-ní.
19 Àmọ́ Íjíbítì yóò di ahoro,+
Édómù yóò sì di aginjù tó dá páropáro,+
Torí bí wọ́n ṣe hùwà ipá sí àwọn ará Júdà,+
Ilẹ̀ àwọn tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.+
20 Àmọ́ àwọn èèyàn á máa gbé ní Júdà nígbà gbogbo,
Àti ní Jerúsálẹ́mù láti ìran dé ìran.+
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ọlọ́run.”
Tàbí “ayé.”
Tàbí “ọmọbìnrin.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “ọkọ.”
Ní Héb., “ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.”
Tàbí “wíìtì.”
Ní Héb., “Ẹ di ara yín lámùrè.”
Tàbí “lu igẹ̀ yín.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Ní Héb., “Ẹ sọ ààwẹ̀ di mímọ́.”
Tàbí kó jẹ́, “ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ.”
Tàbí “ayé.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “ohun ọṣẹ́.”
Tàbí “wíńdò.”
Tàbí “ó jẹ́ olóore ọ̀fẹ́.”
Tàbí “yí ìpinnu pa dà.”
Tàbí “yí ìpinnu pa dà.”
Ní Héb., “Ẹ sọ ààwẹ̀ di mímọ́.”
Tàbí “àgbààgbà.”
Ní Héb., “yàrá ìgbéyàwó.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Ní Héb., “yóò kọjú sí ọ̀nà òkun.”
Ìyẹn, Òkun Òkú.
Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.
Tàbí “àmì.”
Tàbí “èéfín tó rí bí òpó.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Adájọ́.”
Ní Héb., “Ẹ sọ ogun di mímọ́.”
Tàbí “aṣóró.”
Tàbí “àwọn alágbára.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “àlejò.”