ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Rúùtù 1:1-4:22
  • Rúùtù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Rúùtù
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Rúùtù

RÚÙTÙ

1 Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí àwọn onídàájọ́+ ń ṣe àbójútó* ní Ísírẹ́lì, ìyàn mú ní ilẹ̀ náà. Ọkùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjì kúrò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà, wọ́n sì lọ ń gbé ní ilẹ̀* Móábù.+ 2 Élímélékì* ni orúkọ ọkùnrin náà, Náómì* ni orúkọ ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì ń jẹ́ Málónì* àti Kílíónì.* Ará Éfúrátà ni wọ́n, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó wà ní Júdà. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Móábù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀.

3 Nígbà tó yá, Élímélékì ọkọ Náómì kú, ó wá ku obìnrin náà àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì. 4 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ náà fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ará Móábù. Ọ̀kan ń jẹ́ Ọ́pà, èkejì sì ń jẹ́ Rúùtù.+ Nǹkan bí ọdún mẹ́wàá ni wọ́n fi gbé ibẹ̀. 5 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ méjèèjì, Málónì àti Kílíónì kú. Bí obìnrin náà ò ṣe ní ọkọ àti ọmọ mọ́ nìyẹn. 6 Òun àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ wá gbéra, wọ́n sì fi ilẹ̀ Móábù sílẹ̀, torí ó ti gbọ́ ní Móábù pé Jèhófà ti ṣíjú àánú wo àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ti ń fún wọn ní oúnjẹ.*

7 Bó ṣe di pé ó fi ibi tó ń gbé ní Móábù sílẹ̀ nìyẹn, ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì tẹ̀ lé e. Bí wọ́n ṣe ń lọ ní ojú ọ̀nà tó lọ sí ilẹ̀ Júdà, 8 Náómì sọ fún ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé: “Ẹ pa dà, kí kálukú yín lọ sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Jèhófà ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí yín+ bí ẹ ṣe ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí àwọn ọkọ yín tó ti kú àti sí èmi náà. 9 Kí Jèhófà fi* kálukú yín lọ́kàn balẹ̀* ní ilé ọkọ tí ẹ máa fẹ́.”+ Ó fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì bú sẹ́kún. 10 Wọ́n sì ń sọ fún un pé: “Rárá o, a máa bá ọ lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ.” 11 Ṣùgbọ́n Náómì sọ pé: “Ẹ pa dà, ẹ̀yin ọmọ mi. Kí nìdí tí ẹ ó fi bá mi lọ? Ṣé mo ṣì lè bí àwọn ọmọ tó máa fẹ́ yín ni?+ 12 Ẹ pa dà, ẹ̀yin ọmọ mi. Ẹ máa lọ, torí mo ti dàgbà ju ẹni tó lè fẹ́ ọkọ. Ká tiẹ̀ wá sọ pé mo lè rí ọkọ fẹ́ ní alẹ́ òní, tí mo sì bímọ, 13 ṣé ẹ máa wá dúró títí wọ́n á fi dàgbà? Ṣé ẹ ò wá ní lọ́kọ nítorí wọn ni? Rárá o, ẹ̀yin ọmọ mi, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí yín bà mí nínú jẹ́ gan-an torí Jèhófà ti bínú sí mi.”+

14 Ni wọ́n bá tún bú sẹ́kún. Lẹ́yìn èyí, Ọ́pà fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì pa dà. Àmọ́ Rúùtù kò fi í sílẹ̀. 15 Torí náà, Náómì sọ pé: “Wò ó! Ìyàwó àbúrò ọkọ rẹ ti pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ àti àwọn ọlọ́run rẹ̀. Ìwọ náà pa dà.”

16 Àmọ́ Rúùtù sọ pé: “Má rọ̀ mí pé kí n fi ọ́ sílẹ̀, pé kí n má ṣe bá ọ lọ; torí ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ, ibi tí o bá sùn ni èmi yóò sùn. Àwọn èèyàn rẹ ni yóò jẹ́ èèyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.+ 17 Ibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, ibẹ̀ sì ni wọn yóò sin mí sí. Kí Jèhófà fi ìyà jẹ mí gan-an bí ohunkóhun yàtọ̀ sí ikú bá yà wá.”

18 Nígbà tí Náómì rí i pé Rúùtù kò fẹ́ fi òun sílẹ̀, kò rọ̀ ọ́ mọ́ pé kó pa dà. 19 Àwọn méjèèjì sì ń lọ títí wọ́n fi dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ Gbàrà tí wọ́n dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, òkìkí wọn kàn káàkiri ìlú náà, àwọn obìnrin ibẹ̀ sì ń sọ pé: “Ṣé Náómì nìyí?” 20 Ó sì ń fèsì pé: “Ẹ má pè mí ní Náómì* mọ́. Márà* ni kí ẹ máa pè mí, torí Olódùmarè ti mú kí ayé mi korò gan-an.+ 21 Ọwọ́ mi kún nígbà tí mo lọ, àmọ́ Jèhófà mú kí n pa dà lọ́wọ́ òfo. Kí nìdí tí ẹ fi ń pè mí ní Náómì, nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà ló kẹ̀yìn sí mi, Olódùmarè ló sì fa àjálù tó bá mi?”+

22 Bí Náómì ṣe pa dà láti ilẹ̀ Móábù+ nìyẹn, òun àti Rúùtù ará Móábù, ìyàwó ọmọ rẹ̀. Wọ́n dé sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì.+

2 Mọ̀lẹ́bí ọkọ Náómì kan wà tó ní ọrọ̀ gan-an, Bóásì+ ni orúkọ rẹ̀, ìdílé Élímélékì ló sì ti wá.

2 Rúùtù ará Móábù sọ fún Náómì pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí oko, kí n lè pèéṣẹ́*+ lára ṣírí ọkà lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni tó bá ṣojúure sí mi.” Torí náà, Náómì sọ fún un pé: “Lọ, ọmọ mi.” 3 Lẹ́yìn náà, ó lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pèéṣẹ́ lẹ́yìn àwọn olùkórè. Láìmọ̀, ó dé oko Bóásì+ tó wá láti ìdílé Élímélékì.+ 4 Ìgbà yẹn ni Bóásì dé láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó sì sọ fún àwọn olùkórè náà pé: “Kí Jèhófà wà pẹ̀lú yín.” Wọ́n sì dáhùn pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ.”

5 Lẹ́yìn náà, Bóásì bi ọkùnrin tó ń bójú tó àwọn olùkórè pé: “Ilé ibo ni obìnrin yìí ti wá?” 6 Ọkùnrin náà dáhùn pé: “Ará Móábù+ ni, òun ló tẹ̀ lé Náómì wá láti ilẹ̀ Móábù.+ 7 Ó bi mí pé, ‘Ẹ jọ̀ọ́, ṣé mo lè pèéṣẹ́+ kí n sì kó àwọn ṣírí* ọkà tí àwọn olùkórè bá fi sílẹ̀?’ Ó sì ti ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀, kódà ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jókòó sí abẹ́ àtíbàbà kó lè sinmi díẹ̀ ni.”

8 Bóásì wá sọ fún Rúùtù pé: “Gbọ́, ọmọ mi. Má lọ pèéṣẹ́ nínú oko míì, má sì lọ sí ibòmíì, tòsí àwọn òṣìṣẹ́ mi obìnrin+ ni kí o máa wà. 9 Ibi tí wọ́n ti ń kórè ni kí o máa wò, kí o sì máa tẹ̀ lé wọn. Mo ti sọ fún àwọn ọkùnrin tó ń bá mi ṣiṣẹ́ pé wọn kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn ọ́.* Tí òùngbẹ bá ń gbẹ ọ́, lọ síbi ìṣà omi, kí o sì mu nínú omi tí àwọn òṣìṣẹ́ mi pọn.”

10 Torí náà, Rúùtù kúnlẹ̀, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀, ó wá sọ fún un pé: “Kí nìdí tí o fi ṣojúure sí mi, kí sì nìdí tí o fi kíyè sí mi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjèjì+ ni mí?” 11 Bóásì dá a lóhùn pé: “Gbogbo ohun tí o ṣe fún ìyá ọkọ rẹ lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ ni wọ́n ti ròyìn fún mi àti bí o ṣe fi bàbá àti ìyá rẹ àti ìlú ìbílẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tí ìwọ kò mọ̀ rí.+ 12 Kí Jèhófà san ẹ̀san ohun tí o ṣe fún ọ,+ kí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí o wá ààbò wá sábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀+ sì fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.” 13 Ó fèsì pé: “Jọ̀wọ́ olúwa mi, jẹ́ kí n rí ojúure rẹ torí o ti tù mí nínú, ọ̀rọ̀ rẹ sì ti fi ìránṣẹ́ rẹ lọ́kàn balẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò sí lára àwọn òṣìṣẹ́ rẹ.”

14 Nígbà tí àkókò oúnjẹ tó, Bóásì sọ fún un pé: “Máa bọ̀ níbí, wá jẹ búrẹ́dì, kí o sì ki èyí tí o bá bù bọ inú ọtí kíkan.” Torí náà, ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olùkórè. Lẹ́yìn náà, Bóásì fún un ní ọkà yíyan, ó jẹ, ó yó, oúnjẹ rẹ̀ sì ṣẹ́ kù. 15 Nígbà tó dìde láti pèéṣẹ́,+ Bóásì pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kó ṣà lára àwọn ṣírí* ọkà tó bọ́ sílẹ̀ pàápàá, ẹ má sì ni ín lára.+ 16 Kí ẹ sì rí i pé ẹ yọ ṣírí ọkà díẹ̀ sílẹ̀ fún un lára èyí tí ẹ ti dì, kí ẹ sì fi wọ́n sílẹ̀ kó lè ṣà wọ́n, ẹ má ṣe bá a sọ ohunkóhun láti dá a dúró.”

17 Torí náà, ó ń pèéṣẹ́ nínú oko títí di ìrọ̀lẹ́.+ Nígbà tó lu ọkà bálì tó kó jọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kún òṣùwọ̀n eéfà* kan. 18 Lẹ́yìn náà, ó gbé e, ó pa dà sínú ìlú, ìyá ọkọ rẹ̀ sì rí ohun tó pèéṣẹ́. Rúùtù tún gbé oúnjẹ tó ṣẹ́ kù+ lẹ́yìn tó jẹun yó lọ́hùn-ún wá sílé, ó sì gbé e fún ìyá ọkọ rẹ̀.

19 Lẹ́yìn náà, ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un pé: “Ibo lo ti pèéṣẹ́ lónìí? Ibo lo sì ti ṣiṣẹ́? Kí Ọlọ́run bù kún ẹni tó ṣojúure sí ọ.”+ Torí náà, ó sọ ọ̀dọ̀ ẹni tó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀, ó ní: “Bóásì ni orúkọ ẹni tí mo ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí.” 20 Náómì wá sọ fún ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé: “Ìbùkún ni fún un látọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí àwọn alààyè àti òkú.”+ Náómì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mọ̀lẹ́bí wa ni ọkùnrin náà.+ Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùtúnrà* wa.”+ 21 Nígbà náà ni Rúùtù ará Móábù sọ pé: “Ó tún sọ fún mi pé, ‘Ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ mi ni kí o wà títí wọ́n á fi parí gbogbo ìkórè oko mi.’”+ 22 Náómì sọ fún Rúùtù ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé: “Ọmọ mi, ó dáa kí o wà lọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ obìnrin ju kí o lọ sí oko ẹlòmíì tí wọ́n á ti máa dà ọ́ láàmú.”

23 Torí náà, ó wà lọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ Bóásì, ó ń pèéṣẹ́ títí ìkórè ọkà bálì+ àti àlìkámà* fi parí. Ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀ ló sì ń gbé.+

3 Náómì ìyá ọkọ rẹ̀ wá sọ fún un pé: “Ọmọ mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí n wá ọkọ míì* fún ọ báyìí,+ kí nǹkan lè lọ dáadáa fún ọ? 2 Ṣé o rántí pé mọ̀lẹ́bí wa+ ni Bóásì tí o máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ obìnrin? Ó máa lọ fẹ́ ọkà bálì ní ibi ìpakà* ní alẹ́ òní. 3 Torí náà, wẹ̀, fi òróró olóòórùn dídùn para, wọ aṣọ,* kí o wá lọ sí ibi ìpakà náà. Má ṣe jẹ́ kó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tó fi máa jẹun tó sì máa mu. 4 Tó bá ti lọ sùn, kíyè sí ibi tó bá dùbúlẹ̀ sí, kí o lọ ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀. Ó máa sọ ohun tó yẹ kí o ṣe fún ọ.”

5 Rúùtù fèsì pé: “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni màá ṣe.” 6 Torí náà, ó lọ sí ibi ìpakà, ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un. 7 Ní gbogbo ìgbà yẹn, Bóásì ń jẹ, ó ń mu, inú rẹ̀ sì ń dùn. Lẹ́yìn náà, ó lọ dùbúlẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ibi tí wọ́n kó ọkà jọ sí. Obìnrin náà sì yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ síbẹ̀, ó ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ Bóásì, ó sì dùbúlẹ̀. 8 Ní ọ̀gànjọ́ òru, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n, ó dìde jókòó, ó rọra tẹ̀ síwájú, ó wá rí i pé obìnrin kan dùbúlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ òun. 9 Ó bi í pé: “Ta nìyí?” Ó fèsì pé: “Èmi Rúùtù ìránṣẹ́ rẹ ni. Jọ̀ọ́ fi aṣọ rẹ* bo ìránṣẹ́ rẹ, torí ìwọ jẹ́ olùtúnrà.”+ 10 Ó wá sọ pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ, ọmọ mi. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o fi hàn lọ́tẹ̀ yìí dáa ju ti ìgbà àkọ́kọ́ lọ,+ torí pé o ò lọ wá ọ̀dọ́kùnrin, ì báà jẹ́ olówó tàbí tálákà. 11 Ọmọ mi, má bẹ̀rù. Gbogbo ohun tí o sọ ni màá ṣe fún ọ,+ kò kúkú sí ẹni tí kò mọ̀ ní ìlú yìí* pé obìnrin àtàtà ni ọ́. 12 Òótọ́ ni pé olùtúnrà+ ni mí, àmọ́ olùtúnrà kan wà tó bá ọ tan jù mí lọ.+ 13 Dúró síbí ní alẹ́ yìí, bó bá tún ọ rà ní àárọ̀ ọ̀la, kò burú! Jẹ́ kó tún ọ rà.+ Àmọ́ bí kò bá fẹ́ tún ọ rà, bí Jèhófà ti ń bẹ, màá tún ọ rà. Torí náà, sùn síbí di àárọ̀.”

14 Ó sì sùn síbi ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di àárọ̀, lẹ́yìn náà, ó dìde kí ilẹ̀ tó mọ́ kí ẹnikẹ́ni má bàa rí i. Bóásì wá sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ̀ pé obìnrin kan wá sí ibi ìpakà.” 15 Ó tún sọ fún un pé: “Mú ìborùn rẹ wá, kí o sì tẹ́ ẹ.” Torí náà, ó tẹ́ ẹ, ọkùnrin náà sì wọn ọkà bálì òṣùwọ̀n mẹ́fà* sínú ìborùn náà, ó sì gbé e rù ú. Lẹ́yìn èyí, ọkùnrin náà lọ sínú ìlú.

16 Rúùtù lọ sọ́dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀, ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í pé: “Báwo nibi tí o lọ,* ọmọ mi?” Ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún un. 17 Ó tún sọ pé: “Ó fún mi ní ọkà bálì òṣùwọ̀n mẹ́fà yìí, ó wá sọ fún mi pé, ‘Má pa dà sọ́dọ̀ ìyá ọkọ rẹ lọ́wọ́ òfo.’” 18 Torí náà, Náómì sọ pé: “Jókòó síbí, ọmọ mi, títí wàá fi mọ ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí, torí ọkùnrin náà kò ní sinmi títí yóò fi yanjú ọ̀rọ̀ náà lónìí.”

4 Bóásì wá lọ sí ẹnubodè ìlú,+ ó sì jókòó síbẹ̀. Sì wò ó, olùtúnrà tí Bóásì sọ̀rọ̀ rẹ̀+ ń kọjá lọ. Ni Bóásì bá sọ pé: “Èèyàn mi,* wá jókòó.” Torí náà, ó yà, ó sì jókòó. 2 Bóásì sì pe mẹ́wàá lára àwọn àgbààgbà ìlú náà,+ ó sọ pé: “Ẹ jókòó.” Wọ́n sì jókòó.

3 Bóásì wá sọ fún olùtúnrà+ náà pé: “Ó di dandan pé kí Náómì tó pa dà láti ilẹ̀ Móábù+ ta ilẹ̀ Élímélékì+ arákùnrin wa. 4 Torí náà, mo rò pé ó yẹ kí n sọ fún ọ nípa rẹ̀ pé, ‘Rà á níṣojú àwọn ará ìlú àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn mi.+ Tí o bá máa tún un rà, tún un rà. Ṣùgbọ́n tí o kò bá ní tún un rà, jọ̀ọ́ sọ fún mi, kí n lè mọ̀, torí ìwọ lo lẹ́tọ̀ọ́ láti tún un rà, èmi ló sì tẹ̀ lé ọ.’” Ó dáhùn pé: “Màá tún un rà.”+ 5 Torí náà, Bóásì sọ pé: “Ní ọjọ́ tí o bá ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Náómì, o tún gbọ́dọ̀ rà á lọ́wọ́ Rúùtù ará Móábù, aya ọkùnrin tó ti kú náà, kí o lè dá orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà pa dà sórí ogún rẹ̀.”+ 6 Olùtúnrà náà fèsì pé: “Mi ò lè tún un rà, torí kí n má bàa run ogún tèmi. Mo yọ̀ǹda fún ọ láti tún un rà, torí mi ò ní lè tún un rà.”

7 Nígbà àtijọ́ ní Ísírẹ́lì, ohun tí wọ́n máa ń ṣe láti mọ ẹni tó ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà àti pàṣípààrọ̀ kí wọ́n lè fìdí káràkátà èyíkéyìí múlẹ̀ ni pé: Ẹnì kan ní láti bọ́ bàtà rẹ̀,+ kó sì fún ẹnì kejì. Bí wọ́n ṣe máa ń fìdí àdéhùn múlẹ̀* ní Ísírẹ́lì nìyẹn. 8 Torí náà, nígbà tí olùtúnrà náà sọ fún Bóásì pé, “Ìwọ ni kí o rà á,” ó bọ́ bàtà rẹ̀. 9 Bóásì wá sọ fún àwọn àgbààgbà àti gbogbo èèyàn náà pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí+ mi lónìí pé mò ń ra gbogbo ohun tó jẹ́ ti Élímélékì àti gbogbo ohun tó jẹ́ ti Kílíónì àti Málónì lọ́wọ́ Náómì. 10 Mo tún ń fi Rúùtù ará Móábù, ìyàwó Málónì, ṣe aya kí n lè dá orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà pa dà sórí ogún rẹ̀,+ kí orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà má bàa pa rẹ́ ní ìdílé rẹ̀, kó má sì pa rẹ́ ní ẹnubodè ìlú. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi lónìí.”+

11 Torí náà, gbogbo àwọn tó wà ní ẹnubodè ìlú àti àwọn àgbààgbà sọ pé: “Àwa jẹ́rìí sí i! Kí Jèhófà jẹ́ kí ìyàwó tó máa tó wọ ilé rẹ dà bíi Réṣẹ́lì àti Líà, àwọn méjì tó kọ́ ilé Ísírẹ́lì.+ Kí nǹkan máa lọ dáadáa fún ọ ní Éfúrátà,+ kí o sì ní orúkọ rere* ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ 12 Kí ọmọ tí Jèhófà yóò fún ọ látọ̀dọ̀ obìnrin yìí+ mú kí ilé rẹ dà bí ilé Pérésì,+ tí Támárì bí fún Júdà.”

13 Lẹ́yìn náà, Bóásì fẹ́ Rúùtù, ó sì di ìyàwó rẹ̀. Ó bá a ní àṣepọ̀, Jèhófà jẹ́ kó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. 14 Àwọn obìnrin wá ń sọ fún Náómì pé: “Jèhófà ni ìyìn yẹ, òun ló jẹ́ kí o rí olùtúnrà lónìí. Kí òkìkí ọmọ náà kàn ní Ísírẹ́lì! 15 Ó* ti mú kí o lókun, yóò sì tọ́jú rẹ tí o bá darúgbó, torí ìyàwó ọmọ rẹ ló bí i. Ìyàwó náà nífẹ̀ẹ́ rẹ,+ ó sì sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ.” 16 Náómì gbé ọmọ náà sí àyà rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. 17 Ìgbà náà ni àwọn obìnrin tó wà ládùúgbò fún ọmọ náà ní orúkọ. Wọ́n sọ pé, “Náómì ti ní ọmọkùnrin kan.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì.+ Òun ló wá bí Jésè,+ bàbá Dáfídì.

18 Ìlà ìdílé* Pérésì+ nìyí: Pérésì bí Hésírónì;+ 19 Hésírónì bí Rámù; Rámù bí Ámínádábù;+ 20 Ámínádábù+ bí Náṣónì; Náṣónì bí Sálímọ́nì; 21 Sálímọ́nì bí Bóásì; Bóásì bí Óbédì; 22 Óbédì bí Jésè;+ Jésè sì bí Dáfídì.+

Ní Héb., “ṣe ìdájọ́.”

Tàbí “agbègbè.”

Ó túmọ̀ sí “Ọba Ni Ọlọ́run Mi.”

Ó túmọ̀ sí “Adùn Mi.”

Ó ṣeé ṣe kó wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí ẹni “tó tètè máa ń rẹ̀ tàbí ẹni tó máa ń ṣàìsàn.”

Ó túmọ̀ sí “Dákúdájí; Ẹni Tó Ń Kú Lọ.”

Ní Héb., “búrẹ́dì.”

Tàbí “fi ẹ̀bùn fún kálukú yín.”

Ní Héb., “ibi ìsinmi.”

Ó túmọ̀ sí “Adùn Mi.”

Ó túmọ̀ sí “Ìkorò.”

Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.

Tàbí kó jẹ́, “ìtí.”

Tàbí “yọ ọ́ lẹ́nu.”

Tàbí kó jẹ́, “ìtí.”

Nǹkan bíi Lítà 22. Wo Àfikún B14.

Tàbí “mọ̀lẹ́bí wa tó ní ẹ̀tọ́ láti ra ohun ìní wa pa dà.”

Tàbí “wíìtì.”

Ní Héb., “ibi ìsinmi.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ.”

Tàbí “etí aṣọ rẹ.”

Ní Héb., “ní gbogbo ẹnubodè àwọn èèyàn mi.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òṣùwọ̀n síà mẹ́fà tàbí nǹkan bíi Lítà 44. Wo Àfikún B14.

Ní Héb., “Ìwọ ta ni?”

Bíbélì kò sọ orúkọ rẹ̀.

Tàbí “jẹ́rìí sí àdéhùn.”

Ní Héb., “kí wọ́n sì máa dárúkọ rẹ.”

Ìyẹn, ọmọ ọmọ Náómì.

Ní Héb., “Ìran.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́