HÓSÍÀ
1 Ọ̀rọ̀ Jèhófà sí Hósíà* ọmọ Béérì, nígbà ayé Ùsáyà,+ Jótámù,+ Áhásì+ àti Hẹsikáyà,+ àwọn ọba Júdà+ àti nígbà ayé Jèróbóámù+ ọmọ Jóáṣì,+ ọba Ísírẹ́lì. 2 Nígbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹnu Hósíà sọ̀rọ̀, Jèhófà sọ fún Hósíà pé: “Lọ, fẹ́ obìnrin oníṣekúṣe* kan, kí o sì ní àwọn ọmọ àlè,* nítorí pé nípasẹ̀ ìṣekúṣe,* ilẹ̀ yìí ti kúrò lẹ́yìn Jèhófà pátápátá.”+
3 Torí náà, ó lọ, ó fẹ́ Gómérì ọmọ Díbíláímù, obìnrin náà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un.
4 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún un pé: “Pe orúkọ rẹ̀ ní Jésírẹ́lì,* torí pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, màá pe ilé Jéhù+ wá jíhìn fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó wáyé ní Jésírẹ́lì, màá sì fòpin sí ìṣàkóso ilé Ísírẹ́lì.+ 5 Ní ọjọ́ yẹn, màá ṣẹ́ ọrun Ísírẹ́lì ní Àfonífojì* Jésírẹ́lì.”
6 Ó tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. Ọlọ́run wá sọ fún Hósíà pé: “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-ruhámà,* torí mi ò ní ṣàánú+ ilé Ísírẹ́lì mọ́, ṣe ni màá lé wọn dà nù.+ 7 Ṣùgbọ́n màá ṣàánú ilé Júdà,+ èmi Jèhófà Ọlọ́run wọn á sì gbà wọ́n là;+ mi ò ní fi ọfà* tàbí idà tàbí ogun tàbí àwọn ẹṣin tàbí àwọn agẹṣin gbà wọ́n là.”+
8 Lẹ́yìn tó gba ọmú lẹ́nu Lo-ruhámà, ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. 9 Ọlọ́run sì sọ pé: “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-ámì,* nítorí ẹ kì í ṣe èèyàn mi, mi ò sì ní jẹ́ tiyín.
10 “Iye àwọn èèyàn* Ísírẹ́lì máa dà bí iyanrìn òkun tí a kò lè díwọ̀n tàbí tí a kò lè kà.+ Níbi tí a ti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kì í ṣe èèyàn mi,’+ a ó pè wọ́n ní, ‘Àwọn ọmọ Ọlọ́run alààyè.’+ 11 A ó sì mú kí àwọn èèyàn Júdà àti ti Ísírẹ́lì ṣọ̀kan,+ wọ́n á yan olórí fún ara wọn, wọ́n á sì jáde kúrò ní ilẹ̀ náà, nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ náà máa jẹ́ ní Jésírẹ́lì.+
2 “Ẹ sọ fún àwọn arákùnrin yín pé, ‘Ẹ̀yin èèyàn mi!’*+
Àti fún àwọn arábìnrin yín pé, ‘Ẹyin obìnrin tí Ọlọ́run ṣàánú!’*+
Kí ó jáwọ́ nínú ìṣekúṣe* rẹ̀
Kí ó sì mú ìwà àgbèrè kúrò láàárín ọmú rẹ̀,
3 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, màá tú u sí ìhòòhò, màá sì jẹ́ kó rí bíi ti ọjọ́ tí wọ́n bí i,
Màá jẹ́ kó rí bí aginjù,
Á sì di ilẹ̀ tí kò lómi,
Màá sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́ títí á fi kú.
4 Mi ò ní ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,
Torí pé ọmọ àlè* ni wọ́n.
5 Nítorí ìyá wọn ti ṣe ìṣekúṣe.*+
Ẹni tó lóyún wọn ti hùwà àìnítìjú,+ torí ó sọ pé,
‘Màá lọ bá àwọn olólùfẹ́ mi àtàtà,+
Àwọn tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi,
Irun àgùntàn àti aṣọ ọ̀gbọ̀,* òróró àti ohun mímu.’
6 Nítorí náà, màá fi ẹ̀gún ṣe ọgbà dí ojú ọ̀nà rẹ̀;
Màá sì mọ ògiri olókùúta dí ojú ọ̀nà rẹ̀,
Kó má bàa rí ọ̀nà kọjá.
Á wá sọ pé, ‘Màá pa dà sọ́dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́,+
Nítorí nǹkan dáa fún mi ní àkókò yẹn ju ti ìgbà yìí lọ.’+
8 Kò mọ̀ pé èmi ló fún un ní ọkà,+ wáìnì tuntun àti òróró,
Àti pé èmi ló fún un ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fàdákà
Àti wúrà tí wọ́n lò fún Báálì.+
9 ‘Torí náà, màá pa dà wá, màá sì kó ọkà mi lọ ní ìgbà ìkórè
Àti wáìnì tuntun mi ní àsìkò rẹ̀,+
Èmi yóò sì já irun àgùntàn mi gbà àti aṣọ ọ̀gbọ̀* mi tí ì bá bo ìhòòhò rẹ̀.
10 Nígbà náà, màá ṣí abẹ́ rẹ̀ síta lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àtàtà,
Ẹnì kankan ò sì ní lè gbà á lọ́wọ́ mi.+
11 Màá fòpin sí gbogbo ìdùnnú rẹ̀,
Àwọn àjọyọ̀ rẹ̀,+ òṣùpá tuntun rẹ̀ àti àwọn sábáàtì rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ìgbà àjọyọ̀ rẹ̀.
12 Màá run àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, tó sọ nípa wọn pé:
“Èrè tí mo gbà ni wọ́n, tí àwọn olólùfẹ́ mi àtàtà fún mi”;
Màá sọ wọ́n di igbó,
Àwọn ẹran inú igbó á sì jẹ wọ́n run.
13 Màá mú kí ó jíhìn nítorí àwọn ọjọ́ tó fi rúbọ sí àwọn ère Báálì,+
Nígbà tó fi òrùka àti ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ara rẹ̀ lóge, tó sì ń tẹ̀ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àtàtà,
Ó sì ti gbàgbé mi,’+ ni Jèhófà wí.
15 Màá dá àwọn ọgbà àjàrà rẹ̀ pa dà fún un láti ìgbà náà lọ,+
Màá sì fi Àfonífojì* Ákórì+ ṣe ọ̀nà ìrètí fún un;
Yóò dáhùn níbẹ̀ bíi ti ìgbà èwe rẹ̀,
Bíi ti ọjọ́ tó kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
18 Ní ọjọ́ yẹn, màá bá àwọn ẹran inú igbó dá májẹ̀mú nítorí wọn,+
Màá sì bá àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ohun tó ń rákò lórí ilẹ̀ dá májẹ̀mú;+
19 Màá fẹ́ ọ fún ara mi títí láé;
Màá sì fẹ́ ọ fún ara mi nínú òdodo àti nínú ìdájọ́ òdodo,
Nínú ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti nínú àánú.+
20 Màá fẹ́ ọ pẹ̀lú òtítọ́,
Dájúdájú, ìwọ yóò sì mọ Jèhófà.’+
21 ‘Ní ọjọ́ yẹn, màá dáhùn,’ ni Jèhófà wí,
‘Màá dá àwọn ọ̀run lóhùn,
Wọ́n á sì dá ilẹ̀ lóhùn;+
22 Ilẹ̀ á sì dá ọkà àti wáìnì tuntun àti òróró lóhùn;
23 Màá gbìn ín bí irúgbìn fún ara mi sórí ilẹ̀,+
Màá sì ṣàánú rẹ̀, bí wọn ò tiẹ̀ ṣàánú rẹ̀;*
Màá sọ fún àwọn tí kì í ṣe èèyàn mi pé:* “Èèyàn mi ni yín”,+
Àwọn náà á sì sọ pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run wa.”’”+
3 Ìgbà náà ni Jèhófà sọ fún mi pé: “Lọ lẹ́ẹ̀kan sí i, nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ tí ọkùnrin míì ti fẹ́, tó sì ń ṣe àgbèrè,+ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn Ísírẹ́lì+ bí wọ́n tilẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run míì,+ tí wọ́n sì fẹ́ràn ìṣù àjàrà gbígbẹ.”*
2 Nítorí náà, mo rà á fún ara mi ní ẹyọ fàdákà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) àti ọkà bálì tó kún òṣùwọ̀n hómérì* kan àtààbọ̀. 3 Nígbà náà, mo sọ fún un pé: “Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni wàá fi jẹ́ tèmi. O ò gbọ́dọ̀ ṣe ìṣekúṣe,* o ò sì gbọ́dọ̀ ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin míì, irú ìwà kan náà ni màá sì hù sí ọ.”*
4 Nítorí pé ìgbà pípẹ́* ni àwọn èèyàn Ísírẹ́lì yóò máa gbé láìní ọba + àti láìní olórí, láìrú ẹbọ àti láìní òpó, láìsí éfódì+ àti ère tẹ́ráfímù.*+ 5 Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn Ísírẹ́lì máa pa dà wá, wọ́n á wá Jèhófà Ọlọ́run wọn+ àti Dáfídì ọba wọn,+ wọ́n á sì gbọ̀n jìnnìjìnnì wá sọ́dọ̀ Jèhófà àti sí oore rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.+
4 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì,
Jèhófà yóò pe àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà lẹ́jọ́,+
Nítorí kò sí òtítọ́ tàbí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ní ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run.+
2 Ìbúra èké, irọ́ pípa+ àti ìpànìyàn+
Olè jíjà àti àgbèrè+ ti gbilẹ̀,
Ìtàjẹ̀sílẹ̀ ń gorí ìtàjẹ̀sílẹ̀.+
3 Ìdí nìyẹn tí ilẹ̀ náà á fi ṣọ̀fọ̀+
Tí gbogbo àwọn tó ń gbé orí rẹ̀ á sì gbẹ dà nù;
Àwọn ẹran inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run,
Àní títí kan àwọn ẹja inú òkun, yóò ṣègbé.
4 “Àmọ́, kí ẹnikẹ́ni má ṣe bá wọn jiyàn tàbí kó bá wọn wí,+
Torí àwọn èèyàn rẹ dà bí àwọn tó ń bá àlùfáà jiyàn.+
5 Torí náà, wọ́n á fẹsẹ̀ kọ ní ọ̀sán gangan,
Wòlíì á sì fẹsẹ̀ kọ pẹ̀lú wọn, bíi pé alẹ́ ni.
Màá sì pa ìyá wọn lẹ́nu mọ́.*
6 A ó pa àwọn èèyàn mi lẹ́nu mọ́,* torí pé wọn kò ní ìmọ̀.
Nítorí pé wọ́n ti kọ̀ láti mọ̀ mí,+
Èmi náà á kọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe àlùfáà mi mọ́;
Àti nítorí pé wọ́n gbàgbé òfin* Ọlọ́run wọn,+
Èmi náà á gbàgbé àwọn ọmọ wọn.
7 Bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe túbọ̀ ń ṣẹ̀ mí.+
Màá sọ ògo wọn di ìtìjú.*
9 Bó ṣe rí fún àwọn èèyàn náà ló ṣe máa rí fún àwọn àlùfáà;
Màá pè wọ́n wá jíhìn nítorí ìwà wọn,
Màá sì san èrè iṣẹ́ wọn pa dà fún wọn.+
10 Wọ́n á jẹun, ṣùgbọ́n wọn kò ní yó.+
12 Àwọn èèyàn mi ń wádìí lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà tí wọ́n fi igi ṣe,
Wọ́n ń ṣe ohun tí ọ̀pá* wọn sọ fún wọn;
Nítorí pé ẹ̀mí ìṣekúṣe* ti mú kí wọ́n ṣìnà,
Ìṣekúṣe* wọn ni kò jẹ́ kí wọ́n tẹrí ba fún Ọlọ́run wọn.
13 Orí àwọn òkè ńlá ni wọ́n ti ń rúbọ,+
Orí àwọn òkè kéékèèké ni wọ́n sì ti ń mú àwọn ẹbọ rú èéfín,
Lábẹ́ àwọn igi ràgàjì* àti àwọn igi tórásì àti onírúurú igi ńlá,+
Torí pé ibòji àwọn igi náà dára.
Ìdí nìyẹn tí àwọn ọmọbìnrin yín fi ń ṣe ìṣekúṣe*
Tí aya àwọn ọmọ yín sì ń ṣe àgbèrè.
14 Èmi kì yóò mú kí àwọn ọmọbìnrin yín jíhìn torí pé wọ́n ṣe ìṣekúṣe*
Àti aya àwọn ọmọ yín torí pé wọ́n ṣe àgbèrè.
Nítorí pé àwọn ọkùnrin yín ń bá àwọn aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́
Wọ́n sì ń rúbọ pẹ̀lú àwọn aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì;
Àwọn èèyàn tí kò lóye+ yìí yóò pa run.
16 Nítorí Ísírẹ́lì ti di alágídí bíi màlúù tó lágídí.+
Ǹjẹ́ Jèhófà yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn bí ọmọ àgbò nínú ibi ìjẹko tó tẹ́jú?*
17 Éfúrémù ti dara pọ̀ mọ́ àwọn òrìṣà.+
Ẹ fi í sílẹ̀!
Àwọn alákòóso* rẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ àbùkù.+
19 Afẹ́fẹ́ yóò gbá a lọ,
Àwọn ẹbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.”
3 Mo mọ Éfúrémù,
Ísírẹ́lì kì í sì í ṣe àjèjì sí mi.
4 Ìṣe wọn kò jẹ́ kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run wọn,
Torí ẹ̀mí ìṣekúṣe* wà ní àárín wọn;+
Wọn ò sì ka Jèhófà sí.
5 Ìwà Ísírẹ́lì ti jẹ́rìí sí i* pé ó gbéra ga;+
Àṣìṣe Ísírẹ́lì àti Éfúrémù ti mú kí wọ́n kọsẹ̀,
Júdà sì ti kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.+
6 Agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn ni wọ́n fi ń wá Jèhófà,
Ṣùgbọ́n wọn kò rí i.
Ó ti kúrò lọ́dọ̀ wọn.+
7 Wọ́n ti hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà,+
Torí wọ́n ti bí àwọn ọmọ àjèjì.
Ní báyìí, kò ní ju oṣù kan lọ tí àwọn àti ìpín* wọn á fi pa run.
8 Ẹ fun ìwo+ ní Gíbíà àti kàkàkí ní Rámà! +
Ẹ kígbe ogun ní Bẹti-áfénì,+ a ó tẹ̀ lé ọ, ìwọ Bẹ́ńjámínì!
9 Éfúrémù, ìwọ yóò di ohun àríbẹ̀rù ní ọjọ́ ìjìyà.+
Mo ti sọ ohun tó dájú pé ó máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
10 Àwọn olórí Júdà dà bí àwọn tó ń sún ààlà sẹ́yìn.+
Èmi yóò da ìbínú ńlá mi sórí wọn bí omi.
11 Éfúrémù rí ìdààmú, ó gba ìdájọ́ tó yẹ,
Nítorí ó ti pinnu láti tẹ̀ lé ọ̀tá rẹ̀.+
12 Torí náà, mo dà bí òólá* sí Éfúrémù
Mo sì dà bí ìdíbàjẹ́ sí ilé Júdà.
13 Nígbà tí Éfúrémù rí i pé òun ń ṣàìsàn, tí Júdà sì rí i pé egbò wà lára òun,
Éfúrémù lọ sí Ásíríà,+ ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá.
Ṣùgbọ́n kò lè mú un lára dá,
Kò sì lè wo egbò rẹ̀ sàn.
14 Màá dà bí ọmọ kìnnìún sí Éfúrémù
Àti bíi kìnnìún* alágbára sí ilé Júdà.
Èmi fúnra mi á fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, màá sì lọ;+
Màá gbé wọn lọ, kò sì sí ẹni tó máa gbà wọ́n sílẹ̀.+
15 Màá lọ, màá sì pa dà sí ipò mi títí wọ́n á fi gba ìyà ẹ̀bi wọn,
Nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìdààmú, wọ́n á wá mi.”+
Ó ti kọ lù wá, ṣùgbọ́n á di ọgbẹ́ wa.
2 Á mú wa sọ jí lẹ́yìn ọjọ́ méjì.
Á gbé wa dìde ní ọjọ́ kẹta,
A ó sì máa wà láàyè níwájú rẹ̀.
3 A ó mọ Jèhófà, a ó sì fi ìtara wá ìmọ̀ rẹ̀.
Jíjáde rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú;
Yóò wá bá wa bí ọ̀wààrà òjò,
Bí òjò ìgbà ìrúwé tó máa ń rin ilẹ̀.”
4 “Kí ni màá ṣe sí ọ̀rọ̀ rẹ, ìwọ Éfúrémù?
Kí ni màá sì ṣe sí ọ̀rọ̀ rẹ, ìwọ Júdà?
Nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o sọ pé o ní dà bí ìkùukùu òwúrọ̀,
Àti bí ìrì tó tètè ń pòórá.
Ìdájọ́ lórí wọn yóò sì tàn bí ìmọ́lẹ̀.+
6 Nítorí pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀* ni inú mi dùn sí, kì í ṣe ẹbọ
Àti ìmọ̀ nípa Ọlọ́run dípò odindi ẹbọ sísun.+
7 Ṣùgbọ́n bí èèyàn lásán-làsàn, wọ́n ti tẹ májẹ̀mú lójú.+
Wọ́n ti hùwà àìṣòótọ́ sí mi ní ilẹ̀ wọn.
9 Ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà dà bí àwọn jàǹdùkú* tó lúgọ de ẹnì kan.
Wọ́n ń pa èèyàn lójú ọ̀nà ní Ṣékémù,+
Torí pé ìwà àìnítìjú ni wọ́n ń hù.
10 Mo ti rí ohun tó burú jáì ní ilé Ísírẹ́lì.
11 Àmọ́, ìwọ Júdà, a ti dá àkókò ìkórè fún ọ,
Nígbà tí mo bá kó àwọn èèyàn mi tó wà ní oko ẹrú pa dà.”+
2 Àmọ́, ọkàn wọn ò sọ fún wọn pé màá rántí gbogbo ìwà ìkà wọn.+
Ní báyìí, ohun tí wọ́n ṣe ti hàn síta;
Wọ́n wà ní iwájú mi.
3 Wọ́n ń fi ìwà ìkà wọn mú inú ọba dùn,
Wọ́n sì ń fi ẹ̀tàn wọn mú inú àwọn ìjòyè dùn.
4 Alágbèrè ni gbogbo wọn,
Ara wọn ń gbóná bí iná ààrò ẹni tó ń ṣe búrẹ́dì,
Tí kò nílò láti kò ó mọ́ látìgbà tó ti po ìyẹ̀fun títí á fi wú.
5 Lọ́jọ́ àjọyọ̀ ọba wa, àwọn ìjòyè ń ṣàìsàn,
Wáìnì ti mú kí wọ́n bínú.+
Ọba ti tẹ́wọ́ gba àwọn afiniṣẹ̀sín.
6 Nítorí wọ́n wá pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn wọn tó ń jó bí iná ààrò.*
Ẹni tó ń ṣe búrẹ́dì fi gbogbo òru sùn;
Ní òwúrọ̀, iná ààrò náà ti ń jó fòfò.
7 Gbogbo wọn gbóná bí ààrò,
Wọ́n sì jẹ àwọn alákòóso* wọn run.
8 Éfúrémù ti dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+
Éfúrémù dà bí àkàrà tí a kò yí ẹ̀yìn rẹ̀ pa dà.
9 Àwọn àjèjì ti gba okun rẹ̀ tán,+ ṣùgbọ́n kò mọ̀.
Irun orí rẹ̀ ti di funfun, síbẹ̀ kò kíyè sí i.
10 Ìwà Ísírẹ́lì ti jẹ́rìí sí i pé ó gbéra ga,+
Síbẹ̀ wọn kò pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wọn,+
Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá a pẹ̀lú adúrú ohun tí wọ́n ṣe yìí.
11 Éfúrémù dà bí àdàbà tó gọ̀, tí kò ní làákàyè.*+
Wọ́n ti ké pe Íjíbítì;+ wọ́n ti lọ sí Ásíríà.+
12 Ibikíbi tí wọn ì báà lọ, màá fi àwọ̀n mi mú wọn.
Màá mú wọn wálẹ̀ bí ẹyẹ ojú ọ̀run.
Màá bá wọn wí lọ́nà tí mo gbà kìlọ̀ fún àpéjọ wọn.+
13 Wọ́n gbé! Torí wọ́n sá kúrò lọ́dọ̀ mi.
Ìparun á bá wọn, torí wọ́n ti ṣẹ̀ mí!
Mo ṣe tán láti rà wọ́n pa dà, àmọ́ wọ́n pa irọ́ mọ́ mi.+
14 Wọn ò ké pè mí látinú ọkàn wọn fún ìrànlọ́wọ́,+
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sunkún ṣáá lórí ibùsùn wọn.
Torí ọkà wọn àti wáìnì tuntun wọn, wọ́n ń fi nǹkan ya ara wọn;
Wọ́n kẹ̀yìn sí mi.
15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo bá wọn wí tí mo sì fún wọn lókun,
Wọ́n kẹ̀yìn sí mi, wọ́n sì ń gbèrò ibi.
Idà ni yóò pa àwọn olórí wọn nítorí ahọ́n wọn mú.
Torí èyí, wọ́n á di ẹni ẹ̀sín ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+
8 “Fi ìwo sí ẹnu rẹ!+
2 Wọ́n ké pè mí, wọ́n ní ‘Ọlọ́run wa, àwa Ísírẹ́lì ti mọ̀ ọ́!’+
3 Ísírẹ́lì ti kọ ohun rere sílẹ̀.+
Kí ọ̀tá máa lépa rẹ̀.
4 Wọ́n ti fi àwọn ọba jẹ, ṣùgbọ́n kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi.
Wọ́n ti yan àwọn ìjòyè, ṣùgbọ́n èmi kò fọwọ́ sí i.
5 Mo ti kọ ọmọ màlúù rẹ sílẹ̀, ìwọ Samáríà.+
Mo bínú sí yín gidigidi.+
Ìgbà wo lẹ máa tó jáwọ́ nínú ìwà àìmọ́?
6 Torí láti Ísírẹ́lì ni èyí ti wá.
Ohun tí oníṣẹ́ ọnà ṣe ni, kì í ṣe Ọlọ́run;
Ọmọ màlúù Samáríà yóò di èérún.
Bí èyíkéyìí bá sì so, àwọn àjèjì* yóò gbé e mì.+
8 Ọ̀tá ló máa gbé Ísírẹ́lì mì.+
Wọ́n á wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+
Bí ohun èlò tí kò wúlò.
9 Nítorí wọ́n ti lọ sí Ásíríà,+ bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó tó dá wà.
Éfúrémù ti lọ gba àwọn aṣẹ́wó láti fi ṣe olólùfẹ́.+
10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn orílẹ̀-èdè ni wọ́n ti gbà wọ́n,
Màá kó àwọn náà jọ;
Wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í jìyà+ nítorí ẹrù tí ọba àti àwọn ìjòyè dì lé wọn.
11 Torí Éfúrémù ti mọ pẹpẹ púpọ̀ kó lè máa dẹ́ṣẹ̀.+
Àwọn pẹpẹ náà ló sì fi ń dẹ́ṣẹ̀.+
13 Wọ́n ń fi ẹran rúbọ sí mi, wọ́n sì jẹ ẹran náà,
Ṣùgbọ́n inú Jèhófà kò dùn sí ẹbọ wọn.+
Ó máa rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, á sì fìyà jẹ wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+
Àmọ́ màá sọ iná sí àwọn ìlú rẹ̀,
Á sì jó àwọn ilé gogoro ìlú kọ̀ọ̀kan run.”+
9 “Má ṣe yọ̀, ìwọ Ísírẹ́lì,+
Má sì dunnú bí àwọn èèyàn.
Nítorí pé ìṣekúṣe* ti mú ọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ.+
O ti nífẹ̀ẹ́ owó iṣẹ́ aṣẹ́wó lórí gbogbo ibi ìpakà.+
2 Àmọ́ ibi ìpakà àti ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì kò ní fún wọn lóúnjẹ,
Wáìnì tuntun á sì já wọn kulẹ̀.+
3 Wọn kò ní gbé ilẹ̀ Jèhófà mọ́;+
Kàkà bẹ́ẹ̀, Éfúrémù á pa dà sí Íjíbítì,
Wọ́n á sì jẹ ohun àìmọ́ ní Ásíríà.+
Wọ́n dà bí oúnjẹ ọ̀fọ̀;
Gbogbo àwọn tó bá jẹ ẹ́ á sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin.
Nítorí àwọn nìkan* ni oúnjẹ wọn wà fún;
Kò ní wọ ilé Jèhófà.
5 Kí lẹ ó ṣe ní ọjọ́ ìpàdé,*
Ní ọjọ́ àjọyọ̀ Jèhófà?
6 Wò ó! wọ́n á ní láti sá lọ nítorí ìparun.+
Íjíbítì á kó wọn jọ,+ Mémúfísì á sì sin wọ́n.+
Èsìsì ló máa bo àwọn ohun iyebíye tí wọ́n fi fàdákà ṣe,
Àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún á sì wà nínú àgọ́ wọn.
Wòlíì wọn á ya òmùgọ̀, ọkùnrin tó ní ìmísí á sì ya wèrè;
Ìkórìíra tí wọ́n ní sí ọ pọ̀, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pọ̀.”
8 Nígbà kan rí, olùṣọ́ + Éfúrémù ń gbọ́ ti Ọlọ́run mi.+
Àmọ́ ní báyìí, ọ̀nà àwọn wòlíì rẹ̀+ dà bíi pańpẹ́ pẹyẹpẹyẹ;
Ìkórìíra wà ní ilé Ọlọ́run rẹ̀.
9 Wọ́n ti lọ jìnnà nínú fífa ìparun, bíi ti ìgbà àwọn ará Gíbíà.+
Ó máa rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, á sì fìyà jẹ wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+
10 “Mo rí Ísírẹ́lì bí ẹni rí èso àjàrà ní aginjù.+
Mo rí àwọn baba ńlá rẹ̀ bí ẹni rí àkọ́so igi ọ̀pọ̀tọ́.
Àmọ́ wọ́n lọ bá Báálì Péórì;+
Wọ́n fi ara wọn fún ohun ìtìjú,*+
Wọ́n di ohun ìríra, wọ́n sì wá dà bí ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́.
11 Ògo Éfúrémù fò lọ bí ẹyẹ;
Kò ní bímọ, kò ní lóyún, kódà ọlẹ̀ kò ní sọ nínú rẹ̀.+
12 Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ wọn dàgbà,
Màá pa wọ́n, tí kò fi ní ku ìkankan;+
Nígbà tí mo bá pa dà lẹ́yìn wọn, wọ́n gbé!+
13 Éfúrémù tí a gbìn sí ibi ìjẹko, dà bíi Tírè+ sí mi;
Ní báyìí, Éfúrémù gbọ́dọ̀ kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún pípa.”
14 Fún wọn ní ohun tó yẹ kí o fún wọn, Jèhófà;
Fún wọn ní ilé ọmọ tí kò lè gba oyún dúró àti ọmú gbígbẹ.*
15 “Gílígálì + ni gbogbo ìwà ibi wọn ti ṣẹlẹ̀, ibẹ̀ ni mo ti kórìíra wọn.
Màá lé wọn kúrò ní ilé mi nítorí iṣẹ́ ibi wọn.+
Mi ò ní nífẹ̀ẹ́ wọn mọ́;+
Gbogbo olórí wọn ya alágídí.
16 A ó gé Éfúrémù lulẹ̀ bí igi.+
Gbòǹgbò wọn á gbẹ dà nù, wọn ò sì ní lè so èso kankan.
Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ, màá pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn.”
10 “Ísírẹ́lì jẹ́ igi àjàrà tí kò dáa* tó ń so èso.+
Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ló ń mú kí àwọn pẹpẹ rẹ̀ pọ̀ sí i;+
Bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń méso jáde, bẹ́ẹ̀ ló ń mú kí àwọn ọwọ̀n òrìṣà rẹ̀ dára sí i.+
Ẹnì kan wà tó máa fọ́ àwọn pẹpẹ wọn, tó sì máa wó àwọn òpó wọn.
3 Wọ́n á sọ pé, ‘Torí a kò bẹ̀rù Jèhófà ni a kò fi ní ọba.+
Kí ni ọba lè ṣe fún wa?’
4 Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ asán, wọ́n ń búra èké,+ wọ́n sì ń dá májẹ̀mú;
Torí náà, ìdájọ́ wọn dà bí ewéko onímájèlé tó hù jáde láàárín àwọn ebè inú oko.+
5 Ẹ̀rù máa ba àwọn tó ń gbé ní Samáríà torí òrìṣà ọmọ màlúù tó wà ní Bẹti-áfénì.+
Àwọn èèyàn rẹ̀ máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀,
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà ọlọ́run àjèjì ibẹ̀, tó máa ń yọ̀ lórí rẹ̀ àti ògo rẹ̀, máa ṣọ̀fọ̀,
Nítorí pé a ó mú un kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ìgbèkùn.
6 A ó mú un wá sí Ásíríà, láti fi ta ọba ńlá lọ́rẹ.+
Ojú á ti Éfúrémù,
Ìtìjú á sì bá Ísírẹ́lì nítorí ìmọ̀ràn tó tẹ̀ lé.+
8 Àwọn ibi gíga Bẹti-áfénì+ tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì,+ máa pa run pátápátá.+
Ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò hù jáde lórí pẹpẹ wọn.+
Àwọn èèyàn yóò sọ fún àwọn òkè ńlá pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀!’
Wọ́n á sì sọ fún àwọn òkè kéékèèké pé, ‘Ẹ wó lù wá!’+
9 Láti ìgbà àwọn ará Gíbíà ni o ti ṣẹ̀,+ ìwọ Ísírẹ́lì.
Síbẹ̀, ìwọ kò jáwọ́.
Ogun kò pa àwọn aláìṣòdodo tó wà ní Gíbíà run pátápátá.
10 Màá bá wọn wí nígbà tí mo bá fẹ́.
Àwọn èèyàn á sì pé lé wọn lórí,
Nígbà tí mo bá so wọ́n mọ́ àṣìṣe wọn méjèèjì.*
11 “Éfúrémù jẹ́ abo ọmọ màlúù tí a fi iṣẹ́ kọ́, tó fẹ́ràn láti máa pa ọkà,
Torí náà, mo dá ọrùn rẹ̀ tó dáa sí.
Ní báyìí, màá mú kí ẹnì kan gun* Éfúrémù.+
Júdà á túlẹ̀; Jékọ́bù á fọ́ ògúlùtu fún un.
12 Ẹ fúnrúgbìn òdodo, kí ẹ sì kórè ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.
Ẹ tú ilẹ̀ tó dáa fún ọ̀gbìn,+
Nígbà tí àkókò ṣì wà láti wá Jèhófà,+
Títí yóò fi wá, tí yóò sì kọ́ yín nínú òdodo.+
13 Àmọ́, ẹ ti túlẹ̀ ìwà burúkú,
Ẹ ti kórè àìṣòdodo,+
Ẹ sì ti jẹ èso ẹ̀tàn;
Nítorí ẹ ti gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀nà yín
Àti àwọn jagunjagun yín.
14 Ariwo ogun máa sọ láàárín àwọn èèyàn rẹ,
Gbogbo ìlú olódi rẹ á sì pa run,+
Bí ìgbà tí Ṣálímánì pa ilé Áríbélì run,
Ní ọjọ́ ogun tí a fọ́ àwọn ìyá mọ́lẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn.
15 Ohun tí a ó ṣe sí ọ nìyí, ìwọ Bẹ́tẹ́lì,+ nítorí ìwà búburú rẹ tó bùáyà.
Ní àfẹ̀mọ́jú, ó dájú pé a ó pa ọba Ísírẹ́lì.”*+
3 Bẹ́ẹ̀ èmi ni mo kọ́ Éfúrémù ní ìrìn,+ tí mo gbé wọn sí apá mi;+
Síbẹ̀ wọn ò gbà pé mo ti mú wọn lára dá.
4 Mo fi okùn inú rere* àti okùn ìfẹ́ fà wọ́n mọ́ra;+
Mo sì dà bí ẹni tó ń yọ àjàgà kúrò ní ọrùn* wọn,
Lẹ́sọ̀lẹsọ̀ sì ni mo gbé oúnjẹ wá fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.
5 Wọn ò ní pa dà sí ilẹ̀ Íjíbítì, Ásíríà ló sì máa jẹ́ ọba wọn,+
Torí pé wọ́n kọ̀ láti pa dà sọ́dọ̀ mi.+
6 Idà á máa jù fìrìfìrì ní àwọn ìlú rẹ̀+
Yóò run ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, yóò sì pa àwọn ará ìlú rẹ̀ run nítorí ètekéte wọn.+
7 Àwọn èèyàn mi ti pinnu láti jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi.+
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pè wọ́n sókè,* kò sí ẹnì kankan tó dìde.
8 Ṣé ó yẹ kí n yọwọ́ lọ́rọ̀ rẹ, ìwọ Éfúrémù?+
Ṣé ó yẹ kí n fà ọ́ lé ọ̀tá lọ́wọ́, ìwọ Ísírẹ́lì?
Ṣé ó yẹ kí n ṣe ọ́ bí Ádímà?
Ṣé ó yẹ kí n ṣe ọ́ bíi Sébóíímù?+
9 Mi ò ní tú ìbínú mi tó ń jó fòfò jáde.
Mi ò ní pa Éfúrémù run mọ́,+
Nítorí Ọlọ́run ni mí, èmi kì í ṣe èèyàn,
Ẹni Mímọ́ tó wà láàárín rẹ;
Mi ò sì ní fi ìbínú wá sọ́dọ̀ rẹ.
10 Wọ́n á máa tẹ̀ lé Jèhófà, á sì ké ramúramù bíi kìnnìún;+
Nígbà tó bá ké ramúramù, àwọn ọmọ rẹ̀ á gbọ̀n jìnnìjìnnì wá láti ìwọ̀ oòrùn.+
11 Wọ́n á gbọ̀n jìnnìjìnnì bí ẹyẹ nígbà tí wọ́n bá jáde kúrò ní Íjíbítì
Àti bí àdàbà tí wọ́n bá kúrò ní ilẹ̀ Ásíríà;+
Màá sì fìdí wọn kalẹ̀ ní ilé wọn,” ni Jèhófà wí.+
12 “Irọ́ ni Éfúrémù ń pa fún mi ṣáá,
Ẹ̀tàn sì ni ilé Ísírẹ́lì ń ṣe sí mi nígbà gbogbo.+
Àmọ́ Júdà ṣì ń bá Ọlọ́run rìn,
Ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Ẹni Mímọ́ Jù Lọ.”+
12 “Ẹ̀fúùfù ni Éfúrémù fi ṣe oúnjẹ.
Ó sì ń sá tẹ̀ lé ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.
Ó mú kí irọ́ àti ìwà ipá pọ̀ sí i.
Ó bá Ásíríà dá májẹ̀mú,+ ó sì gbé òróró lọ sí Íjíbítì.+
2 Jèhófà máa pe Júdà lẹ́jọ́;+
Ó máa pe Jékọ́bù wá jíhìn nítorí àwọn ọ̀nà rẹ̀,
Ó sì máa san án lẹ́san àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+
3 Nígbà tó wà nínú ìyá rẹ̀, ó gbá arákùnrin rẹ̀ mú ní gìgísẹ̀,+
Ó sì fi gbogbo okun rẹ̀ bá Ọlọ́run wọ̀jà.+
4 Ó bá áńgẹ́lì kan jà títí ó fi borí.
Ó sunkún, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣojúure sí òun.”+
6 “Torí náà, pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ,+
Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìdájọ́ òdodo bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́,+
Sì máa ní ìrètí nínú Ọlọ́run rẹ nígbà gbogbo.
Nínú gbogbo làálàá mi, wọn ò ní rí àìtọ́ tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan.’
9 Ṣùgbọ́n èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti ilẹ̀ Íjíbítì wá.+
Màá tún mú kí o máa gbé inú àwọn àgọ́
Bí ìgbà àkókò tí a ti yàn.*
11 Ẹ̀tàn*+ àti àìṣòótọ́ ti wà ní Gílíádì.
Wọ́n ti fi àwọn akọ màlúù rúbọ ní Gílígálì,+
Àwọn pẹpẹ wọn sì dà bí àwọn òkúta tí a tò jọ sí àárín àwọn ebè inú oko.+
12 Jékọ́bù sá lọ sí agbègbè* Árámù;*+
Ísírẹ́lì+ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ nítorí àtifẹ́ ìyàwó,+
Ó sì ń da àgùntàn nítorí ìyàwó.+
14 Éfúrémù ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì;+
Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó ta sílẹ̀ wà lórí rẹ̀;
Olúwa rẹ̀ á sì san án lẹ́san ẹ̀gàn rẹ̀.”+
13 “Nígbà tí Éfúrémù sọ̀rọ̀, ẹ̀rù ba àwọn èèyàn;
Torí pé ẹni ńlá ni ní Ísírẹ́lì.+
Àmọ́, ó jẹ̀bi nítorí ó sin Báálì,+ ó sì kú.
2 Ní báyìí, wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀
Wọ́n sì fi fàdákà+ wọn ṣe ère onírin;*
Wọ́n ṣe àwọn òrìṣà lọ́nà tó já fáfá, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ ohun tí oníṣẹ́ ọnà ṣe.
Wọ́n sọ nípa wọn pé, ‘Kí àwọn tó wá rúbọ fi ẹnu ko àwọn ọmọ màlúù lẹ́nu.’+
3 Torí náà, wọ́n á dà bí ìkùukùu òwúrọ̀,
Bí ìrì tó tètè ń pòórá,
Bí ìyàngbò* tí ìjì gbé lọ kúrò ní ibi ìpakà
Àti bí èéfín tó jáde látinú ihò òrùlé.
4 Ṣùgbọ́n èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti ilẹ̀ Íjíbítì wá;+
Ìwọ kò sì mọ Ọlọ́run mìíràn àfi èmi,
Lẹ́yìn mi kò sí olùgbàlà kankan.+
5 Mo mọ̀ ọ́ ní aginjù,+ ní ilẹ̀ aláìlómi.
Torí náà, wọ́n gbàgbé mi.+
7 Màá dà bí ọmọ kìnnìún sí wọn,+
Bí àmọ̀tẹ́kùn tó lúgọ sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà.
8 Màá bẹ́ mọ́ wọn bíi bíárì tí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ nù,
Màá sì fa àyà* wọn ya.
Màá jẹ wọ́n níbẹ̀ bíi kìnnìún;
Ẹran inú igbó yóò fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
9 Yóò pa ọ́ run, ìwọ Ísírẹ́lì,
Torí pé o ti kẹ̀yìn sí èmi olùrànlọ́wọ́ rẹ.
10 Ibo wá ni ọba rẹ wà, kí ó lè gbà ọ́ ní gbogbo ìlú rẹ+
Àti àwọn alákòóso* rẹ, tí o sọ nípa wọn pé,
‘Fún mi ní ọba àti àwọn ìjòyè’?+
12 A ti di* àṣìṣe Éfúrémù pa mọ́;
A sì ti to ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ.
13 Ìrora ìgbà ìbímọ yóò dé bá a.
Àmọ́, ọmọ tí kò gbọ́n ni;
Ó kọ̀ láti jáde nígbà tí ìyá rẹ̀ fẹ́ bí i.
Ìwọ Ikú, oró rẹ dà?+
Ìwọ Isà Òkú, ìpanirun rẹ dà?+
Síbẹ̀, mi ò ní fojú àánú wò wọ́n.*
15 Bó bá tiẹ̀ gbilẹ̀ láàárín àwọn esùsú,*
Ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn yóò wá, ẹ̀fúùfù Jèhófà,
Yóò wá láti aṣálẹ̀, yóò sì mú kí kànga àti odò rẹ̀ gbẹ.
Ẹnì kan máa wá kó gbogbo ohun iyebíye tó wà ní ilé ìṣúra rẹ̀.+
16 A ó dá Samáríà lẹ́bi,+ torí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run rẹ̀.+
14 “Pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì,+
Torí àṣìṣe rẹ ti mú kí o kọsẹ̀.
2 Ẹ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,
Ẹ sọ fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,+ kí o sì gba ohun rere tí a mú wá,
A ó sì fi ètè wa rú ẹbọ ìyìn sí ọ+ bí ẹni fi akọ ọmọ màlúù rúbọ.*
3 Ásíríà kò ní lè gbà wá là.+
A ò ní gun ẹṣin,+
A ò sì tún ní máa pe iṣẹ́ ọwọ́ wa ní, “Ọlọ́run wa!”
Nítorí pé ìwọ lò ń ṣàánú ọmọ aláìníbaba.’+
4 Màá wo àìṣòótọ́ wọn sàn.+
5 Màá máa sẹ̀ bí ìrì sórí Ísírẹ́lì;
Á yọ ìtànná bí òdòdó lílì
Á sì ta gbòǹgbò rẹ̀ bí àwọn igi Lẹ́bánónì.
6 Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ á tẹ́ rẹrẹ,
Ògo rẹ̀ á dà bíi ti igi ólífì,
Ìtasánsán rẹ̀ á sì dà bíi ti Lẹ́bánónì.
7 Àwọn èèyàn mi á pa dà máa gbé lábẹ́ òjìji mi.
Wọ́n á gbin ọkà, wọ́n á sì yọ ìtànná bí àjàrà.+
Òkìkí* rẹ̀ á dà bíi ti wáìnì Lẹ́bánónì.
8 Éfúrémù á sọ pé, ‘Kí ni mo tún fẹ́ wá lọ sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà?’+
Màá dáhùn, màá sì máa ṣọ́ ọ.+
Màá dà bí igi júnípà tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.
Wàá sì máa rí èso lọ́dọ̀ mi.”
9 Ta ni ó gbọ́n? Kí ó lóye nǹkan wọ̀nyí.
Ta ni ó lóye? Kí ó mọ̀ wọ́n.
Nítorí àwọn ọ̀nà Jèhófà tọ́,+
Àwọn olódodo yóò sì máa rìn nínú wọn;
Àmọ́, àwọn tó ń dẹ́ṣẹ̀ yóò kọsẹ̀ nínú wọn.
Ìkékúrú Hóṣáyà, tó túmọ̀ sí “Jáà Ló Gbà Á Là; Jáà Ti Gbà Á Là.”
Tàbí “aṣẹ́wó.”
Tàbí “aṣẹ́wó.”
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Yóò Fún Irúgbìn.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ó túmọ̀ sí “A Kò Fi Àánú Hàn sí I.”
Ní Héb., “ọrun.”
Ó túmọ̀ sí “Kì Í Ṣe Èèyàn Mi.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Wo Ho 1:9 àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Wo Ho 1:6 àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Tàbí “aṣẹ́wó.”
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “Báálì Mi.”
Ní Héb., “ọrun.”
Tàbí “gbé.”
Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Yóò Fún Irúgbìn.”
Wo Ho 1:6 àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Wo Ho 1:9 àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Ìyẹn, èyí tí wọ́n ń lò nínú ìjọsìn èké.
Hómérì kan jẹ́ òṣùwọ̀n tó gba Lítà 220. Wo Àfikún B14.
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Tàbí “mi ò ní ní àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ.”
Ní Héb., “ọjọ́ púpọ̀.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “pa ìyá wọn run.”
Tàbí “pa àwọn èèyàn mi run.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n ti fi ìtìjú rọ́pò ògo mi.”
Ìyẹn, àwọn àlùfáà.
Tàbí “gbé ọkàn sókè sí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “oníṣekúṣe paraku; aṣẹ́wó.”
Tàbí “Iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Ní Héb., “ń mú ọkàn kúrò.”
Tàbí “ọ̀pá woṣẹ́woṣẹ́.”
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Tàbí “Iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Tàbí “igi óákù.”
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Ní Héb., “ibi aláyè gbígbòòrò?”
Tàbí “bíà tí wọ́n fi wíìtì ṣe.”
Tàbí “oníṣekúṣe paraku; aṣẹ́wó.”
Ní Héb., “Àwọn apata.”
Tàbí “Àwọn tó yapa.”
Tàbí “jingíri sínú.”
Tàbí “Màá bá gbogbo wọn wí.”
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Ní Héb., “fi hàn lójú rẹ̀.”
Tàbí “ilẹ̀.”
Tàbí “kòkòrò.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Ní Héb., “ojú.”
Tàbí “àánú.”
Tàbí “àwọn akónilẹ́rù.”
Tàbí “àwọn akónilẹ́rù.”
Tàbí kó jẹ́, “Nítorí ọkàn wọn dà bí iná ààrò bí wọ́n ṣe ń bọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ wọn.”
Ní Héb., “àwọn onídàájọ́.”
Ní Héb., “tí kò ní ọkàn.”
Ìyẹn, ìjọsìn tòótọ́.
Tàbí “dúró.”
Tàbí “àlejò.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́, “Wọn yóò pa dà.”
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Tàbí “ọkàn wọn nìkan.”
Tàbí “ní ọjọ́ àsè tí ẹ yàn.”
Tàbí “ọlọ́run tó ń tini lójú.”
Tàbí “pẹlẹbẹ.”
Tàbí kó jẹ́, “tó ń gbalẹ̀.”
Tàbí “Ẹ̀tàn.”
Ní Héb., “ni a ó pa lẹ́nu mọ́.”
Ìyẹn, nígbà tí wọ́n bá ru ìyà wọn bí àjàgà.
Tàbí “fi ìjánu sí.”
Ní Héb., “pa ọba Ísírẹ́lì lẹ́nu mọ́.”
Ìyẹn, àwọn wòlíì àti àwọn míì tí Ọlọ́run rán láti tọ́ Ísírẹ́lì sọ́nà.
Ní Héb., “okùn èèyàn.”
Ní Héb., “ẹ̀rẹ̀kẹ́.”
Ìyẹn, ìjọsìn tó ga.
Ní Héb., “ìyọ́nú mi ti gbóná.”
Tàbí “orúkọ ìrántí rẹ̀.”
Tàbí “olówò.”
Tàbí kó jẹ́, “àjọyọ̀.”
Tàbí “Ohun abàmì; Ohun àdììtú.”
Ní Héb., “ilẹ̀.”
Tàbí “Síríà.”
Tàbí “ère dídà.”
Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.
Ní Héb., “igbá àyà.”
Ní Héb., “onídàájọ́.”
Tàbí “tọ́jú.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ìyẹn, torí pé wọ́n ṣì wà nínú ẹ̀ṣẹ̀. Wo ẹsẹ 12.
Ìyẹn, koríko etí omi.
Ní Héb., “A ó rú ẹbọ akọ ọmọ màlúù ètè wa pa dà sí ọ.”
Ní Héb., “Ìrántí.”