ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Ẹ́sítérì 1:1-10:3
  • Ẹ́sítà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ́sítà
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́sítà

Ẹ́SÍTÀ

1 Nígbà ayé Ahasuérúsì,* ìyẹn Ahasuérúsì tó ṣàkóso ìpínlẹ̀* mẹ́tàdínláàádóje+ (127) láti Íńdíà títí dé Etiópíà,* 2 lákòókò yẹn, Ọba Ahasuérúsì wà lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá,* 3 ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè ńlá fún gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Páṣíà+ àti Mídíà,+ àwọn èèyàn pàtàkì àti àwọn olórí ìpínlẹ̀* wà níwájú rẹ̀, 4 ó sì fi ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ ológo àti ọlá ńlá àti ẹwà títóbi rẹ̀ hàn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ìyẹn ọgọ́sàn-án (180) ọjọ́. 5 Nígbà tí àwọn ọjọ́ náà parí, ọba se àsè ńlá ní ọjọ́ méje fún gbogbo àwọn tó wà ní Ṣúṣánì* ilé ńlá,* látorí ẹni ńlá dórí ẹni kékeré ní àgbàlá tó wà ní ọgbà ààfin ọba. 6 Wọ́n fi okùn aṣọ àtàtà ta aṣọ ọ̀gbọ̀ àti aṣọ olówùú múlọ́múlọ́ àti aṣọ aláwọ̀ búlúù; òwú aláwọ̀ pọ́pù tí wọ́n so mọ́ àwọn òrùka fàdákà ni wọ́n fi ta wọ́n mọ́ àwọn òpó tí wọ́n fi òkúta mábù ṣe. Àwọn àga tìmùtìmù wúrà àti fàdákà sì wà lórí ibi tí wọ́n fi òkúta pọ́fírì àti òkúta mábù pẹ̀lú péálì àti òkúta mábù dúdú tẹ́.

7 Ife* wúrà ni wọ́n fi ń gbé wáìnì fúnni; àwọn ife náà yàtọ̀ síra, wáìnì tí ọba pèsè sì pọ̀ gan-an bí ọlá ọba ṣe pọ̀ tó. 8 Òfin tí wọ́n tẹ̀ lé ni pé kí wọ́n má fi dandan lé* iye ọtí tí ẹnì kan máa mu, torí ọba ti sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ tó wà ní ààfin rẹ̀ pé kí kálukú ṣe bó ṣe fẹ́.

9 Bákan náà, Fáṣítì Ayaba+ se àsè ńlá fún àwọn obìnrin ní ilé* Ọba Ahasuérúsì.

10 Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì ń mú inú ọba dùn,* ó sọ fún Méhúmánì, Bísítà, Hábónà,+ Bígítà, Ábágítà, Sétárì àti Kákásì, àwọn òṣìṣẹ́ méje tó wà láàfin tí wọ́n jẹ́ ẹmẹ̀wà* Ọba Ahasuérúsì fúnra rẹ̀, 11 pé kí wọ́n lọ mú Fáṣítì Ayaba wá síwájú ọba pẹ̀lú ìwérí ayaba* lórí rẹ̀, láti fi ẹwà rẹ̀ han àwọn èèyàn àti àwọn ìjòyè, nítorí ó lẹ́wà gan-an. 12 Ṣùgbọ́n Fáṣítì Ayaba kọ̀, kò wá ní gbogbo ìgbà tí àwọn òṣìṣẹ́ ààfin wá jíṣẹ́ ọba fún un. Nítorí náà, inú bí ọba gidigidi, ó sì gbaná jẹ.

13 Ọba wá sọ fún àwọn ọlọgbọ́n èèyàn tó ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ìlànà* (bí ọ̀rọ̀ ọba ṣe dé iwájú gbogbo àwọn tó mọ òfin àti ẹjọ́ dunjú nìyẹn, 14 àwọn tó sún mọ́ ọn jù lọ ni Káṣénà, Ṣétárì, Ádímátà, Táṣíṣì, Mérésì, Másénà àti Mémúkánì, àwọn ìjòyè méje+ láti Páṣíà àti Mídíà, tí wọ́n máa ń wá sọ́dọ̀ ọba, tí wọ́n sì wà ní ipò tó ga jù nínú ìjọba náà). 15 Ọba béèrè pé: “Gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe sọ, kí ni ká ṣe sí Fáṣítì Ayaba nítorí kò tẹ̀ lé àṣẹ tí Ọba Ahasuérúsì pa láti ẹnu àwọn òṣìṣẹ́ ààfin?”

16 Ni Mémúkánì bá fèsì níwájú ọba àti àwọn ìjòyè pé: “Kì í ṣe ọba nìkan ni Fáṣítì Ayaba ṣe ohun tí kò dáa sí,+ ó tún kan gbogbo àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn èèyàn ní gbogbo ìpínlẹ̀* Ọba Ahasuérúsì. 17 Nítorí gbogbo àwọn aya á gbọ́ ohun tí ayaba ṣe, wọn ò sì ní ka ọkọ wọn sí, wọ́n á máa sọ pé, ‘Ọba Ahasuérúsì sọ pé kí wọ́n mú Fáṣítì Ayaba wá síwájú òun, àmọ́ ó kọ̀, kò wá.’ 18 Lónìí yìí, àwọn ìyàwó ìjòyè Páṣíà àti Mídíà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ayaba ṣe á máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba, èyí á sì yọrí sí ọ̀pọ̀ ẹ̀gàn àti ìbínú. 19 Tó bá dáa lójú ọba, kó pa àṣẹ kan, kí wọ́n sì kọ ọ́ sínú àwọn òfin Páṣíà àti Mídíà tí kò ṣeé yí pa dà,+ pé kí Fáṣítì má ṣe wá síwájú Ọba Ahasuérúsì mọ́ láé; kí ọba sì fi ipò ayaba fún obìnrin tó sàn jù ú lọ. 20 Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ àṣẹ tí ọba pa ní gbogbo ilẹ̀ àkóso rẹ̀ tó fẹ̀, gbogbo àwọn aya á máa bọlá fún ọkọ wọn, látorí ẹni ńlá dórí ẹni kékeré.”

21 Àbá yìí dára lójú ọba àti àwọn ìjòyè, ọba sì ṣe ohun tí Mémúkánì sọ. 22 Nítorí náà, ó fi àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àṣẹ ọba,+ sí ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé tirẹ̀ àti sí àwùjọ èèyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè tirẹ̀, pé kí ọkọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ olórí* ní ilé rẹ̀, èdè àwọn èèyàn rẹ̀ ni kó sì máa sọ.

2 Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, nígbà tí ìbínú Ọba Ahasuérúsì+ rọlẹ̀, ó rántí ohun tí Fáṣítì ṣe+ àti ohun tí wọ́n ti pinnu láti ṣe sí i.+ 2 Àwọn ẹmẹ̀wà* ọba wá sọ pé: “Jẹ́ kí a wá àwọn ọ̀dọ́bìnrin, àwọn wúńdíá tó rẹwà fún ọba. 3 Kí ọba yan àwọn kọmíṣọ́nnà ní gbogbo ìpínlẹ̀* tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀+ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó jẹ́ wúńdíá arẹwà jọ sí Ṣúṣánì* ilé ńlá,* ní ilé àwọn obìnrin.* Kí a fi wọ́n sábẹ́ àbójútó Hégáì+ ìwẹ̀fà ọba, olùtọ́jú àwọn obìnrin, kí wọ́n sì máa gba ìtọ́jú aṣaralóge.* 4 Ọ̀dọ́bìnrin tó bá wu ọba jù lọ ló máa di ayaba dípò Fáṣítì.”+ Àbá náà dára lójú ọba, ohun tó sì ṣe nìyẹn.

5 Ọkùnrin Júù kan wà ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá,* Módékáì+ lorúkọ rẹ̀, ó jẹ́ ọmọ Jáírì, ọmọ Ṣíméì, ọmọ Kíṣì, ọmọ Bẹ́ńjámínì,+ 6 ẹni tí wọ́n mú láti Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n kó mọ́ Jekonáyà*+ ọba Júdà, tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì mú lọ sí ìgbèkùn. 7 Módékáì yìí ni alágbàtọ́* Hádásà,* ìyẹn Ẹ́sítà, tó jẹ́ ọmọ arákùnrin bàbá rẹ̀,+ torí kò ní bàbá àti ìyá. Ọ̀dọ́bìnrin náà lẹ́wà gan-an, ìrísí rẹ̀ sì fani mọ́ra, nígbà tí bàbá àti ìyá rẹ̀ kú, Módékáì mú un ṣe ọmọ. 8 Nígbà tí wọ́n kéde ọ̀rọ̀ ọba àti òfin rẹ̀, tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin jọ sí Ṣúṣánì* ilé ńlá* lábẹ́ àbójútó Hégáì,+ wọ́n mú Ẹ́sítà náà wá sí ilé* ọba lábẹ́ àbójútó Hégáì, olùtọ́jú àwọn obìnrin.

9 Ọ̀dọ́bìnrin náà dára lójú rẹ̀, ó sì rí ojú rere* rẹ̀, torí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ṣètò bí wọ́n á ṣe máa fún un ní ìtọ́jú aṣaralóge*+ àti oúnjẹ tí á máa jẹ, ó sì fún un ní àṣàyàn ọ̀dọ́bìnrin méje láti ilé ọba. Ó tún fi òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sí ibi tó dára jù lọ ní ilé àwọn obìnrin.* 10 Ẹ́sítà ò sọ nǹkan kan nípa àwọn èèyàn rẹ̀+ tàbí nípa àwọn ìbátan rẹ̀, torí Módékáì+ ti sọ fún un pé kó má sọ fún ẹnikẹ́ni.+ 11 Ojoojúmọ́ ni Módékáì máa ń gba iwájú àgbàlá ilé àwọn obìnrin* kọjá, kó lè wo àlàáfíà Ẹ́sítà àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí i.

12 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà ló ní ìgbà tí wọ́n máa wọlé sọ́dọ̀ Ọba Ahasuérúsì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí ìtọ́jú olóṣù méjìlá tí wọ́n ní kí wọ́n fún àwọn obìnrin, nítorí ohun tí ìtọ́jú aṣaralóge* náà gbà nìyẹn, wọ́n á fi oṣù mẹ́fà lo òróró òjíá,+ wọ́n á sì fi oṣù mẹ́fà lo òróró básámù+ pẹ̀lú oríṣiríṣi òróró ìpara tí wọ́n fi ń ṣe ìtọ́jú aṣaralóge.* 13 Lẹ́yìn ìyẹn, ọ̀dọ́bìnrin náà ti ṣe tán láti wọlé sọ́dọ̀ ọba, ohunkóhun tó bá béèrè ni wọ́n máa fún un nígbà tó bá fẹ́ kúrò ní ilé àwọn obìnrin* lọ sí ilé ọba. 14 Ní ìrọ̀lẹ́, á wọlé, á sì pa dà ní àárọ̀ sí ilé kejì tó jẹ́ ti àwọn obìnrin* lábẹ́ àbójútó Ṣááṣígásì ìwẹ̀fà ọba,+ olùtọ́jú àwọn wáhàrì.* Kò tún ní wá sọ́dọ̀ ọba mọ́, àfi tí ọba bá dìídì fẹ́ràn rẹ̀, tó sì dárúkọ rẹ̀ pé kí wọ́n lọ pè é wá.+

15 Nígbà tó kan Ẹ́sítà ọmọ Ábíháílì arákùnrin òbí Módékáì, ẹni tó mú un ṣe ọmọ,+ láti wọlé lọ bá ọba, kò béèrè ohunkóhun lẹ́yìn ohun tí Hégáì ìwẹ̀fà ọba, olùtọ́jú àwọn obìnrin, fún un. (Ní gbogbo àkókò yìí, Ẹ́sítà ń rí ojú rere gbogbo àwọn tó rí i). 16 Wọ́n mú Ẹ́sítà lọ sọ́dọ̀ Ọba Ahasuérúsì ní ilé ọba ní oṣù kẹwàá, ìyẹn oṣù Tébétì,* ní ọdún keje+ ìjọba rẹ̀. 17 Ọba wá nífẹ̀ẹ́ Ẹ́sítà ju gbogbo àwọn obìnrin yòókù lọ, ó sì rí ojú rere àti ìtẹ́wọ́gbà* rẹ̀ ju gbogbo àwọn wúńdíá yòókù. Torí náà, ó fi ìwérí* ayaba sí i lórí, ó sì fi í ṣe ayaba+ dípò Fáṣítì.+ 18 Ọba se àsè ńlá fún gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àkànṣe àsè nítorí Ẹ́sítà. Lẹ́yìn náà, ó kéde ìtúsílẹ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀,* ó sì ń fún àwọn èèyàn lẹ́bùn bí ọrọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó.

19 Nígbà tí wọ́n kó àwọn wúńdíá*+ jọ nígbà kejì, Módékáì ń jókòó ní ẹnubodè ọba. 20 Ẹ́sítà kò sọ nǹkan kan nípa àwọn ìbátan rẹ̀ àti àwọn èèyàn rẹ̀,+ bí Módékáì ṣe pa á láṣẹ fún un; Ẹ́sítà ń ṣe ohun tí Módékáì sọ, bí ìgbà tó ṣì wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀.+

21 Lákòókò yẹn, nígbà tí Módékáì ń jókòó ní ẹnubodè ọba,* inú bí méjì lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba tó jẹ́ aṣọ́nà, Bígítánì àti Téréṣì, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa* Ọba Ahasuérúsì. 22 Àmọ́ Módékáì gbọ́ ohun tó ń lọ, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì sọ fún Ẹ́sítà Ayaba. Ẹ́sítà wá sọ fún ọba ní orúkọ Módékáì.* 23 Torí náà, wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì rí i nígbà tó yá pé òótọ́ ni, wọ́n wá gbé àwọn méjèèjì kọ́ sórí òpó igi; wọ́n kọ gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ níṣojú ọba, sínú ìwé ìtàn àkókò náà.+

3 Lẹ́yìn èyí, Ọba Ahasuérúsì gbé Hámánì+ ọmọ Hamédátà ọmọ Ágágì+ ga, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ti gbogbo àwọn ìjòyè yòókù tí wọ́n jọ wà.+ 2 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ọba tó wà ní ẹnubodè ọba máa ń tẹrí ba fún Hámánì, wọ́n sì ń wólẹ̀ fún un, nítorí ohun tí ọba pàṣẹ pé kí wọ́n máa ṣe fún un nìyẹn. Àmọ́ Módékáì kọ̀, kò tẹrí ba fún un, kò sì wólẹ̀. 3 Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ ọba tó wà ní ẹnubodè ọba béèrè lọ́wọ́ Módékáì pé: “Kí ló dé tí o kò fi pa àṣẹ ọba mọ́?” 4 Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́ kì í fetí sí wọn. Wọ́n wá sọ fún Hámánì láti mọ̀ bóyá ohun tí Módékáì ń ṣe bójú mu;+ torí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun.+

5 Nígbà tí Hámánì rí i pé Módékáì kọ̀, kò tẹrí ba fún òun, tí kò sì wólẹ̀, Hámánì gbaná jẹ.+ 6 Àmọ́ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn láti pa* Módékáì nìkan, torí wọ́n ti sọ fún un nípa àwọn èèyàn Módékáì. Nítorí náà, Hámánì bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasuérúsì run, ìyẹn gbogbo àwọn èèyàn Módékáì.

7 Ní oṣù kìíní, ìyẹn oṣù Nísàn,* ọdún+ kejìlá Ọba Ahasuérúsì, wọ́n ṣẹ́ Púrì,+ (ìyẹn Kèké) níwájú Hámánì láti mọ ọjọ́ àti oṣù, ó sì bọ́ sí oṣù kejìlá, oṣù Ádárì.*+ 8 Hámánì wá sọ fún Ọba Ahasuérúsì pé: “Àwọn èèyàn kan wà káàkiri tí wọ́n ń dá tiwọn ṣe láàárín àwọn èèyàn+ tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀* tó wà lábẹ́ àkóso rẹ,+ òfin wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn èèyàn yòókù; wọn kì í sì í pa òfin ọba mọ́, wọ́n á pa ọba lára tí a bá fi wọ́n sílẹ̀ bẹ́ẹ̀. 9 Tó bá dáa lójú ọba, kí ó pa àṣẹ kan, kí wọ́n sì kọ ọ́ sílẹ̀ pé kí a pa wọ́n run. Màá fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ńtì* fàdákà pé kí wọ́n kó o sínú ibi ìṣúra ọba.”*

10 Ọba wá bọ́ òrùka àṣẹ+ ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún Hámánì + ọmọ Hamédátà ọmọ Ágágì,+ ẹni tó jẹ́ ọ̀tá àwọn Júù. 11 Ọba sọ fún Hámánì pé: “A fún ọ ní fàdákà àti àwọn èèyàn náà, ohun tó bá wù ọ́ ni kí o ṣe sí wọn.” 12 Wọ́n wá pe àwọn akọ̀wé ọba+ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìíní. Wọ́n kọ+ gbogbo àṣẹ tí Hámánì pa fún àwọn baálẹ̀ ọba, àwọn gómìnà tó ń ṣàkóso àwọn ìpínlẹ̀* àti àwọn olórí àwùjọ èèyàn lóríṣiríṣi, wọ́n kọ ọ́ sí ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé tirẹ̀ àti sí àwùjọ àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn. Wọ́n kọ ọ́ ní orúkọ Ọba Ahasuérúsì, wọ́n sì fi òrùka àṣẹ ọba gbé èdìdì lé e.+

13 Wọ́n fi àwọn lẹ́tà náà rán àwọn asáréjíṣẹ́ sí gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àṣẹ ọba, láti fi pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù, kí wọ́n run wọ́n, kí wọ́n sì pa wọ́n rẹ́, lọ́mọdé lágbà, àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn obìnrin, lọ́jọ́ kan náà, ìyẹn lọ́jọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Ádárì,+ kí wọ́n sì gba àwọn ohun ìní wọn.+ 14 Kí wọ́n fi ẹ̀dà lẹ́tà náà ṣe òfin fún ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n sì kéde rẹ̀ fún gbogbo èèyàn, kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ náà. 15 Àwọn asáréjíṣẹ́ náà jáde lọ kíákíá+ bí ọba ṣe pa á láṣẹ; wọ́n gbé òfin náà jáde ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá.* Ọba àti Hámánì wá jókòó láti mutí, àmọ́ ìlú Ṣúṣánì* wà nínú ìdàrúdàpọ̀.

4 Nígbà tí Módékáì+ gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ṣe,+ ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀,* ó sì da eérú sórí. Ó wá lọ sí àárín ìlú, ó gbé ohùn sókè, ó sì ń sunkún kíkankíkan. 2 Ó ń lọ títí ó fi dé ẹnubodè ọba, àmọ́ kò wọlé, torí ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ ọ̀fọ̀* wọ ẹnubodè ọba. 3 Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ láàárín àwọn Júù tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀*+ tí ọ̀rọ̀ ọba àti àṣẹ rẹ̀ ti dé, wọ́n ń gbààwẹ̀,+ wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń pohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀ lára wọn sùn sórí aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú.+ 4 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́bìnrin Ẹ́sítà àti àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ wọlé wá, tí wọ́n sì sọ fún un, ìdààmú bá ayaba gidigidi. Ó wá fi aṣọ ránṣẹ́ sí Módékáì, pé kó wọ̀ ọ́ dípò aṣọ ọ̀fọ̀* tó wà lọ́rùn rẹ̀, àmọ́ kò gbà á. 5 Ni Ẹ́sítà bá pe Hátákì, ọ̀kan lára àwọn ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ọba yàn láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún Ẹ́sítà, ó sì ní kó lọ béèrè lọ́wọ́ Módékáì ohun tí èyí túmọ̀ sí àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀.

6 Torí náà, Hátákì lọ bá Módékáì ní gbàgede ìlú tó wà níwájú ẹnubodè ọba. 7 Módékáì sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i fún Hátákì àti iye owó+ tí Hámánì sọ pé òun máa san sínú ibi ìṣúra ọba kí wọ́n lè pa àwọn Júù run.+ 8 Ó tún fún un ní ẹ̀dà ìwé àṣẹ tí wọ́n gbé jáde ní Ṣúṣánì*+ láti pa wọ́n run. Ó ní kó fi han Ẹ́sítà, kó ṣàlàyé rẹ̀ fún un, kó sì sọ fún un+ pé kó lọ bá ọba láti wá ojú rere rẹ̀, kí òun fúnra rẹ̀ sì bá àwọn èèyàn rẹ̀ bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ọba.

9 Hátákì pa dà, ó sì jíṣẹ́ Módékáì fún Ẹ́sítà. 10 Ẹ́sítà ní kí Hátákì lọ ṣàlàyé fún Módékáì+ pé: 11 “Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ọba àti àwọn èèyàn tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ abẹ́ àṣẹ ọba ló mọ̀ pé, tí ọkùnrin tàbí obìnrin èyíkéyìí bá wọlé lọ bá ọba ní àgbàlá inú+ láìjẹ́ pé ọba pè é, òfin kan ṣoṣo tí wọ́n máa tẹ̀ lé ni pé: Kí wọ́n pa onítọ̀hún; àyàfi tí ọba bá na ọ̀pá àṣẹ wúrà+ sí i ni kò ní kú. Ó sì ti tó ọgbọ̀n (30) ọjọ́ báyìí tí wọn ò tíì pè mí sọ́dọ̀ ọba.”

12 Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Ẹ́sítà fún Módékáì, 13 ó fún Ẹ́sítà lésì pé: “Má rò pé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn Júù yòókù kò ní kàn ọ́ torí pé o wà nínú agbo ilé ọba. 14 Tí o bá dákẹ́ ní àkókò yìí, àwọn Júù máa rí ìtura àti ìdáǹdè láti ibòmíì,+ ṣùgbọ́n ìwọ àti ilé bàbá rẹ yóò ṣègbé. Ta ló sì mọ̀ bóyá torí irú àkókò yìí lo fi dé ipò ayaba tí o wà?”+

15 Nígbà náà, Ẹ́sítà fún Módékáì lésì pé: 16 “Lọ, kó gbogbo àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì* jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀+ nítorí mi. Ẹ má jẹ, ẹ má sì mu fún ọjọ́ mẹ́ta,+ ní òru àti ní ọ̀sán. Èmi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi á sì gbààwẹ̀ bákan náà. Màá wọlé lọ sọ́dọ̀ ọba, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò bá òfin mu, tí mo bá sì máa kú, kí n kú.” 17 Torí náà, Módékáì lọ, ó sì ṣe gbogbo ohun tí Ẹ́sítà sọ pé kó ṣe.

5 Ní ọjọ́ kẹta,+ Ẹ́sítà wọ aṣọ ayaba, ó sì dúró ní àgbàlá inú ilé* ọba ní òdìkejì ààfin ọba, ọba jókòó lórí ìtẹ́ nínú ilé ọba tó wà ní òdìkejì ẹnu ọ̀nà. 2 Bí ọba ṣe rí Ẹ́sítà Ayaba tó dúró ní àgbàlá, ó rí ojú rere ọba, ọba sì na ọ̀pá àṣẹ wúrà+ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ sí Ẹ́sítà. Ẹ́sítà sún mọ́ tòsí, ó sì fọwọ́ kan orí ọ̀pá àṣẹ náà.

3 Ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ́sítà Ayaba, ṣé kò sí o? Kí lo fẹ́ béèrè? Kódà tí ó bá tó* ìdajì ìjọba mi, a ó fi fún ọ!” 4 Ẹ́sítà fèsì pé: “Tó bá dáa lójú ọba, kí ọba àti Hámánì+ wá lónìí síbi àsè tí mo ti sè fún ọba.” 5 Torí náà, ọba sọ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ sọ fún Hámánì pé kó wá kíákíá, gẹ́gẹ́ bí Ẹ́sítà ṣe sọ.” Ọba àti Hámánì sì lọ síbi àsè tí Ẹ́sítà sè.

6 Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, nígbà tí wọ́n ń mu wáìnì lọ́wọ́, ọba sọ fún Ẹ́sítà pé: “Kí lo fẹ́ tọrọ? A ó fi fún ọ! Kí lo sì fẹ́ béèrè? Kódà tí ó bá tó* ìdajì ìjọba mi, a ó ṣe é fún ọ!”+ 7 Ẹ́sítà dáhùn, ó ní: “Ohun tí mo fẹ́ tọrọ, tí mo sì fẹ́ béèrè ni pé, 8 Tí mo bá rí ojú rere ọba, tó bá sì wu ọba láti ṣe ohun tí mo fẹ́, kó sì fún mi ní ohun tí mo béèrè, kí ọba àti Hámánì wá síbi àsè tí màá sè fún wọn lọ́la; ọ̀la ni màá sì béèrè ohun tí ọba ní kí n béèrè.”

9 Lọ́jọ́ náà, tayọ̀tayọ̀ ni Hámánì fi jáde lọ, inú rẹ̀ sì ń dùn. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hámánì rí Módékáì ní ẹnubodè ọba, tó sì rí i pé kò dìde, kò sì wárìrì níwájú òun, inú bí Hámánì gan-an sí Módékáì.+ 10 Àmọ́, Hámánì pa á mọ́ra, ó sì lọ sí ilé rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ránṣẹ́ pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti Séréṣì+ ìyàwó rẹ̀. 11 Hámánì wá ń fọ́nnu nípa ọlá ńlá rẹ̀, bí àwọn ọmọ rẹ̀+ ṣe pọ̀ tó, bí ọba ṣe gbé e ga àti bó ṣe gbé e lékè àwọn ìjòyè àti àwọn ìránṣẹ́ ọba.+

12 Hámánì tún sọ pé: “Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, èmi nìkan ni Ẹ́sítà Ayaba ní kó bá ọba wá síbi àsè tó sè.+ Ó tún pè mí pé kí n wá lọ́la sọ́dọ̀ òun àti ọba.+ 13 Àmọ́ gbogbo èyí kò tíì tẹ́ mi lọ́rùn tí mo bá ṣì ń rí Módékáì, Júù tó ń jókòó ní ẹnubodè ọba.” 14 Torí náà, Séréṣì aya rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Jẹ́ kí wọ́n gbé òpó igi kan nàró, kí ó ga ní àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́.* Tó bá di àárọ̀, sọ fún ọba pé kí wọ́n gbé Módékáì kọ́ sórí rẹ̀.+ Lẹ́yìn náà, kí o bá ọba lọ gbádùn ara rẹ níbi àsè náà.” Àbá yìí dára lójú Hámánì, torí náà ó ní kí wọ́n gbé òpó igi kan nàró.

6 Ní òru ọjọ́ yẹn, ọba ò rí oorun sùn.* Torí náà, ó ní kí wọ́n mú ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn àwọn àkókò+ wá, wọ́n sì kà á fún ọba. 2 Nínú àkọsílẹ̀ náà, wọ́n rí ohun tí Módékáì sọ nípa Bígítánà àti Téréṣì, àwọn òṣìṣẹ́ méjì láàfin ọba tí wọ́n jẹ́ aṣọ́nà, àwọn tó gbìmọ̀ pọ̀ láti pa* Ọba Ahasuérúsì.+ 3 Ọba wá béèrè pé: “Ọlá àti iyì wo la ti fún Módékáì nítorí ohun tó ṣe yìí?” Àwọn ẹmẹ̀wà* ọba sọ pé: “A kò tíì ṣe nǹkan kan fún un.”

4 Lẹ́yìn náà, ọba sọ pé: “Ta ló wà ní àgbàlá?” Ní àkókò yìí, Hámánì ti dé sí àgbàlá ìta+ ilé* ọba láti sọ fún ọba bí wọ́n ṣe máa gbé Módékáì kọ́ sórí òpó igi tó ti ṣe fún un.+ 5 Àwọn ẹmẹ̀wà* ọba sọ fún un pé: “Hámánì+ ni, ó dúró ní àgbàlá.” Ọba wá sọ pé: “Ẹ jẹ́ kó wọlé.”

6 Nígbà tí Hámánì wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló yẹ ká ṣe fún ọkùnrin tó wu ọba pé kó dá lọ́lá?” Hámánì sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Ta ni ọba tún fẹ́ dá lọ́lá tí kì í bá ṣe èmi?”+ 7 Nítorí náà, Hámánì sọ fún ọba pé: “Ní ti ọkùnrin tó wu ọba pé kó dá lọ́lá, 8 jẹ́ kí wọ́n mú ẹ̀wù oyè+ tí ọba máa ń wọ̀ àti ẹṣin tí ọba máa ń gùn, kí wọ́n sì fi ìwérí ọba sí orí ẹṣin náà. 9 Kí wọ́n fi ẹ̀wù oyè àti ẹṣin náà síkàáwọ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè pàtàkì, kí wọ́n wọ aṣọ náà fún ọkùnrin tó wu ọba pé kó dá lọ́lá, kí wọ́n sì mú un gun ẹṣin náà ní gbàgede ìlú. Kí wọ́n máa kéde níwájú rẹ̀ pé: ‘Ohun tí wọ́n máa ń ṣe nìyí fún ẹni tó wu ọba pé kó dá lọ́lá!’”+ 10 Lójú ẹsẹ̀, ọba sọ fún Hámánì pé: “Ṣe kíá! Mú ẹ̀wù oyè àti ẹṣin náà, kí o sì ṣe ohun tí o sọ yìí fún Módékáì, Júù tó ń jókòó ní ẹnubodè ọba. Má yọ ìkankan sílẹ̀ nínú gbogbo ohun tí o sọ.”

11 Torí náà, Hámánì mú ẹ̀wù oyè àti ẹṣin náà, ó wọ aṣọ náà fún Módékáì,+ ó sì mú un gun ẹṣin ní gbàgede ìlú, ó ń kéde níwájú rẹ̀ pé: “Ohun tí wọ́n máa ń ṣe nìyí fún ẹni tó wu ọba pé kó dá lọ́lá!” 12 Lẹ́yìn náà, Módékáì pa dà sí ẹnubodè ọba, àmọ́ Hámánì yára lọ sí ilé rẹ̀, ó ń ṣọ̀fọ̀, ó sì bo orí rẹ̀. 13 Hámánì sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i fún Séréṣì+ aya rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Nígbà náà, àwọn amòye rẹ̀ àti Séréṣì aya rẹ̀ sọ fún un pé: “Tó bá jẹ́ pé àtọmọdọ́mọ* Júù ni Módékáì tí o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣubú níwájú rẹ̀ yìí, á jẹ́ pé o ò ní borí rẹ̀; ó sì dájú pé wàá ṣubú níwájú rẹ̀.”

14 Bí wọ́n ṣe ń bá a sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba dé, wọ́n sì yára mú Hámánì lọ síbi àsè tí Ẹ́sítà ti sè.+

7 Nígbà náà, ọba àti Hámánì+ wá sí ibi àsè Ẹ́sítà Ayaba. 2 Ọba tún béèrè lọ́wọ́ Ẹ́sítà ní ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n ń mu wáìnì lọ́wọ́ pé: “Ẹ́sítà Ayaba, kí lo fẹ́ tọrọ? A ó fi fún ọ. Kí lo sì fẹ́ béèrè? Kódà tí ó bá tó* ìdajì ìjọba mi, a ó ṣe é fún ọ!”+ 3 Ẹ́sítà Ayaba fèsì pé: “Tí mo bá rí ojú rere rẹ, ọba, tó bá sì wu ọba, ohun tí mo fẹ́ tọrọ ni pé kí a fún mi ní ẹ̀mí* mi, ohun tí mo sì fẹ́ béèrè ni pé kí a fún mi ní àwọn èèyàn mi.+ 4 Nítorí wọ́n ti ta+ èmi àti àwọn èèyàn mi, láti pa wá, láti run wá àti láti pa wá rẹ́.+ Ká ní wọ́n kàn tà wá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin nìkan ni, mi ò bá dákẹ́. Àmọ́ àjálù náà kò ní bọ́ sí i rárá torí pé ó máa pa ọba lára.”

5 Ọba Ahasuérúsì wá béèrè lọ́wọ́ Ẹ́sítà Ayaba pé: “Ta ni? Ibo lẹni tó gbójúgbóyà ṣerú èyí wà?” 6 Ẹ́sítà sọ pé: “Elénìní àti ọ̀tá náà ni Hámánì olubi yìí.”

Jìnnìjìnnì bo Hámánì nítorí ọba àti ayaba. 7 Ọba fi ìbínú dìde kúrò nídìí wáìnì, ó sì lọ sí ọgbà ààfin, àmọ́ Hámánì dìde láti bẹ Ẹ́sítà Ayaba nítorí ẹ̀mí* rẹ̀, torí ó mọ̀ pé ọba ti pinnu láti fìyà jẹ òun. 8 Ọba pa dà wá láti ọgbà ààfin sí ilé tí wọ́n ti ń mu wáìnì, ó sì rí Hámánì tó nà lé àga tìmùtìmù tí Ẹ́sítà wà. Ọba kọ hàà pé: “Ṣé ó tún fẹ́ fipá bá ayaba lò pọ̀ nínú ilé mi ni?” Bí ọba ṣe sọ ọ̀rọ̀ yìí tán, wọ́n bo Hámánì lójú. 9 Hábónà,+ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba wá sọ pé: “Hámánì tún ṣe òpó igi kan fún Módékáì,+ ẹni tó sọ ohun tó gba ọba sílẹ̀.+ Òpó náà wà ní òró ní ilé Hámánì, àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́* ni gíga rẹ̀.” Ni ọba bá sọ pé: “Ẹ gbé e kọ́ sórí rẹ̀.” 10 Torí náà, wọ́n gbé Hámánì kọ́ sórí òpó igi tó ṣe fún Módékáì, ìbínú ọba sì rọlẹ̀.

8 Ní ọjọ́ yẹn, Ọba Ahasuérúsì fún Ẹ́sítà Ayaba ní ilé Hámánì,+ ọ̀tá àwọn Júù;+ Módékáì sì wá síwájú ọba torí pé Ẹ́sítà ti sọ bó ṣe jẹ́ sí òun.+ 2 Ọba wá bọ́ òrùka àṣẹ+ rẹ̀ tó gbà lọ́wọ́ Hámánì, ó sì fún Módékáì. Ẹ́sítà sì fi Módékáì ṣe olórí ilé Hámánì.+

3 Bákan náà, Ẹ́sítà tún bá ọba sọ̀rọ̀. Ó wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń sunkún, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó yí jàǹbá tí Hámánì ọmọ Ágágì fẹ́ ṣe pa dà àti ohun tó gbèrò láti ṣe sí àwọn Júù.+ 4 Ọba na ọ̀pá àṣẹ wúrà sí Ẹ́sítà,+ ni Ẹ́sítà bá dìde, ó sì dúró níwájú ọba. 5 Ó sọ pé: “Tó bá dáa lójú ọba, tí mo bá sì rí ojú rere rẹ̀, tó bá yẹ lójú ọba, tó sì fẹ́ràn mi, jẹ́ kí wọ́n kọ ìwé àṣẹ kan láti fagi lé ìwé àṣẹ tí Hámánì elétekéte+ ọmọ Hamédátà ọmọ Ágágì+ kọ, èyí tó kọ pé kí wọ́n pa àwọn Júù tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀ abẹ́ àṣẹ ọba run. 6 Nítorí ara mi ò lè gbà á pé kí n máa wo àjálù tó máa dé bá àwọn èèyàn mi, ara mi ò sì ní gbà á pé kí àwọn ìbátan mi pa run.”

7 Nítorí náà, Ọba Ahasuérúsì sọ fún Ẹ́sítà Ayaba àti Módékáì tó jẹ́ Júù pé: “Ẹ wò ó! Mo ti fún Ẹ́sítà ní ilé Hámánì,+ mo sì ti ní kí wọ́n gbé e kọ́ sórí òpó igi,+ nítorí ète tó pa láti gbéjà ko* àwọn Júù. 8 Ní báyìí, ẹ kọ ohunkóhun tó bá dáa lójú yín lórúkọ ọba nítorí àwọn Júù, kí ẹ sì fi òrùka àṣẹ ọba gbé èdìdì lé e, nítorí ìwé àṣẹ tí wọ́n bá kọ lórúkọ ọba, tí wọ́n sì fi òrùka àṣẹ ọba gbé èdìdì lé kò ṣeé yí pa dà.”+

9 Torí náà, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba ní àkókò yẹn ní oṣù kẹta, ìyẹn oṣù Sífánì,* ní ọjọ́ kẹtàlélógún, wọ́n sì kọ gbogbo ohun tí Módékáì pa láṣẹ fún àwọn Júù àti fún àwọn baálẹ̀,+ fún àwọn gómìnà àti àwọn ìjòyè àwọn ìpínlẹ̀*+ tó wà ní Íńdíà títí dé Etiópíà, ìpínlẹ̀ mẹ́tàdínláàádóje (127), wọ́n kọ ọ́ sí ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé tirẹ̀ àti sí àwùjọ èèyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè tirẹ̀, bákan náà, wọ́n kọ ọ́ sí àwọn Júù ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé wọn àti ní èdè wọn.

10 Ó kọ ọ́ ní orúkọ Ọba Ahasuérúsì, ó fi òrùka àṣẹ ọba+ gbé èdìdì lé e, ó sì fi àwọn ìwé náà rán àwọn asáréjíṣẹ́ tó ń gun ẹṣin; ẹṣin àfijíṣẹ́ tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá nílẹ̀ ni wọ́n gùn, iṣẹ́ ọba sì ni àwọn ẹṣin náà wà fún. 11 Nínú ìwé náà, ọba fún àwọn Júù tó wà ní gbogbo ìlú kọ̀ọ̀kan láyè láti kóra jọ, kí wọ́n sì gbèjà ara* wọn, kí wọ́n pa àwọn ọmọ ogun àwùjọ tàbí ti ìpínlẹ̀* èyíkéyìí tó bá gbéjà kò wọ́n, títí kan àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn obìnrin, kí wọ́n run wọ́n, kí wọ́n pa wọ́n rẹ́, kí wọ́n sì gba ohun ìní wọn.+ 12 Ọjọ́ kan náà ni kí èyí ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àṣẹ Ọba Ahasuérúsì, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, ìyẹn oṣù Ádárì.*+ 13 Kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ inú* ìwé náà ṣe òfin káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀.* Kí wọ́n kéde rẹ̀ fún gbogbo àwọn èèyàn, kí àwọn Júù lè múra sílẹ̀ lọ́jọ́ náà láti gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn.+ 14 Àwọn asáréjíṣẹ́ tó ń gun ẹṣin àfijíṣẹ́ tó wà fún iṣẹ́ ọba sáré jáde lọ kíákíá gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe pa á láṣẹ. Wọ́n sì tún gbé òfin náà jáde ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá.*

15 Módékáì wá jáde níwájú ọba nínú ẹ̀wù oyè olówùú búlúù àti funfun,* ó dé adé ńlá tí wọ́n fi wúrà ṣe, ó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè àtàtà olówùú pọ́pù.+ Igbe ayọ̀ sì sọ ní ìlú Ṣúṣánì.* 16 Àwọn Júù rí ìtura,* wọ́n ń yọ̀, inú wọn ń dùn, wọ́n sì ń ṣògo. 17 Ní gbogbo ìpínlẹ̀* àti gbogbo ìlú tí àṣẹ ọba àti òfin rẹ̀ dé, àwọn Júù ń yọ̀, inú wọn ń dùn, wọ́n ń se àsè, wọ́n sì ń ṣe àjọyọ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í pe ara wọn ní Júù,+ torí ẹ̀rù àwọn Júù ń bà wọ́n.

9 Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, ìyẹn oṣù Ádárì,*+ nígbà tí ó tó àkókò láti mú ọ̀rọ̀ ọba àti òfin rẹ̀ ṣẹ,+ ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá àwọn Júù ti dúró dè láti ṣẹ́gun wọn, ọ̀tọ̀ lohun tó ṣẹlẹ̀, àwọn Júù ṣẹ́gun àwọn tó kórìíra wọn.+ 2 Àwọn Júù kóra jọ ní àwọn ìlú wọn ní gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àṣẹ Ọba Ahasuérúsì,+ láti gbéjà ko àwọn tó fẹ́ ṣe wọ́n ní jàǹbá, kò sì sí ẹni tó lè dúró níwájú wọn, nítorí ẹ̀rù wọn ń ba gbogbo àwọn èèyàn.+ 3 Gbogbo àwọn olórí tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀,* àwọn baálẹ̀,+ àwọn gómìnà àti àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ọba ń ti àwọn Júù lẹ́yìn, torí ẹ̀rù Módékáì ń bà wọ́n. 4 Módékáì ti di alágbára+ ní ilé* ọba, òkìkí rẹ̀ sì ń kàn káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀,* torí ńṣe ni agbára Módékáì ń pọ̀ sí i.

5 Àwọn Júù fi idà ṣá gbogbo àwọn ọ̀tá wọn balẹ̀, wọ́n ń pa wọ́n, wọ́n sì ń run wọ́n; wọ́n ṣe ohun tó wù wọ́n sí àwọn tó kórìíra wọn.+ 6 Ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá,* àwọn Júù pa ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọkùnrin, wọ́n sì run wọ́n. 7 Wọ́n tún pa Páṣáńdátà, Dálífónì, Ásípátà, 8 Pọ́rátà, Adalíà, Árídátà, 9 Pámáṣítà, Árísáì, Árídáì àti Fáísátà, 10 àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hámánì ọmọ Hamédátà, ọ̀tá àwọn Júù.+ Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n pa wọ́n, wọn ò kó ohun ìní èyíkéyìí.+

11 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n ròyìn iye àwọn tí wọ́n pa ní Ṣúṣánì* ilé ńlá* fún ọba.

12 Ọba sọ fún Ẹ́sítà Ayaba pé: “Ní Ṣúṣánì* ilé ńlá,* àwọn Júù ti pa ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Kí ni wọ́n ṣe ní àwọn ìpínlẹ̀ abẹ́ àṣẹ ọba yòókù?+ Ní báyìí, kí lohun tí o fẹ́ tọrọ? A ó fi fún ọ. Kí lo sì tún fẹ́ béèrè? A ó ṣe é fún ọ.” 13 Ẹ́sítà fèsì pé: “Tó bá dáa lójú ọba,+ jẹ́ kí a fún àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì* láyè lọ́la láti ṣe ohun tí òfin ti òní sọ;+ sì jẹ́ kí wọ́n gbé àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kọ́ sórí òpó igi.”+ 14 Torí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n ṣe òfin kan ní Ṣúṣánì,* wọ́n sì gbé àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kọ́.

15 Àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì* tún kóra jọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì,+ wọ́n sì pa ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin ní Ṣúṣánì,* àmọ́ wọn ò kó ohun ìní èyíkéyìí.

16 Bákan náà, ìyókù àwọn Júù tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ abẹ́ àṣẹ ọba kóra jọ, wọ́n sì gbèjà ara* wọn.+ Wọ́n rẹ́yìn àwọn ọ̀tá wọn,+ ẹgbẹ̀rún márùnléláàádọ́rin (75,000) lára àwọn tó kórìíra wọn ni wọ́n pa; àmọ́ wọn ò kó ohun ìní èyíkéyìí. 17 Ọjọ́ kẹtàlá oṣù Ádárì ni èyí ṣẹlẹ̀, ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sinmi, wọ́n sì fi ṣe ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀.

18 Àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì* kóra jọ ní ọjọ́ kẹtàlá+ àti ní ọjọ́ kẹrìnlá,+ wọ́n sinmi ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, wọ́n sì fi ṣe ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀. 19 Ìdí nìyẹn tí àwọn Júù ìgbèríko tó ń gbé ní àwọn ìlú tó wà ní àwọn agbègbè tó jìnnà ṣe fi ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì ṣe ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àsè, ọjọ́ àjọyọ̀  + àti àkókò láti fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí ara wọn.+

20 Módékáì+ kọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sílẹ̀, ó sì fi àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀ abẹ́ àṣẹ Ọba Ahasuérúsì, àwọn tó wà nítòsí àti àwọn tó wà lọ́nà jíjìn. 21 Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì àti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù náà mọ́ lọ́dọọdún, 22 torí ní àwọn ọjọ́ yẹn, àwọn Júù sinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, oṣù yẹn ni ìbànújẹ́ wọn di ayọ̀, tí ọ̀fọ̀+ wọn sì di àjọyọ̀. Ó ní kí wọ́n máa fi àwọn ọjọ́ náà ṣe ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀ àti àkókò láti fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí ara wọn àti láti máa fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn aláìní.

23 Àwọn Júù gbà láti máa ṣe àjọyọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ náà lọ àti láti máa ṣe ohun tí Módékáì kọ ránṣẹ́ sí wọn. 24 Hámánì+ ọmọ Hamédátà, ọmọ Ágágì,+ ọ̀tá gbogbo àwọn Júù ti gbèrò láti pa àwọn Júù run,+ ó ti ṣẹ́ Púrì,+ ìyẹn Kèké, láti kó ìpayà bá wọn, kí ó sì pa wọ́n run. 25 Àmọ́ nígbà tí Ẹ́sítà wá síwájú ọba, ọba pa àṣẹ kan tí wọ́n kọ sílẹ̀ pé:+ “Kí èrò ibi tí ó gbà sí àwọn Júù+ pa dà sórí rẹ̀”; wọ́n sì gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí òpó igi.+ 26 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe àwọn ọjọ́ náà ní Púrímù, látinú orúkọ Púrì.*+ Nítorí gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú lẹ́tà yìí àti ohun tí wọ́n rí nípa ọ̀ràn yìí àti ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn, 27 àwọn Júù sọ ọ́ di dandan fún ara wọn àti fún àtọmọdọ́mọ wọn pẹ̀lú gbogbo àwọn tó dara pọ̀ mọ́ wọn+ láti máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ méjèèjì yìí láìjẹ́ kó yẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó wà lákọsílẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ náà ní àkókò tí wọ́n bọ́ sí lọ́dọọdún. 28 Kí ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan àti ìlú kọ̀ọ̀kan máa rántí àwọn ọjọ́ yìí, kí wọ́n sì máa pa wọ́n mọ́ láti ìran dé ìran; àwọn ọjọ́ Púrímù yìí kò gbọ́dọ̀ yẹ̀ láàárín àwọn Júù, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn sì gbọ́dọ̀ máa ṣe ìrántí wọn títí láé.

29 Ẹ́sítà Ayaba, ọmọ Ábíháílì àti Módékáì tó jẹ́ Júù fi gbogbo àṣẹ tí wọ́n ní kọ̀wé láti fìdí lẹ́tà kejì nípa Púrímù múlẹ̀. 30 Módékáì fi àwọn lẹ́tà tó ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́ ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù ní ìpínlẹ̀* mẹ́tàdínláàádóje+ (127) tó wà lábẹ́ àkóso Ahasuérúsì,+ 31 láti fìdí pípa àwọn ọjọ́ Púrímù yìí mọ́ múlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n bọ́ sí, gẹ́gẹ́ bí Módékáì tó jẹ́ Júù àti Ẹ́sítà Ayaba ṣe ní kí wọ́n ṣe+ àti bí wọ́n ṣe sọ ọ́ di dandan fún ara* wọn àti àwọn àtọmọdọ́mọ wọn láti máa ṣe é+ pẹ̀lú ààwẹ̀+ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.+ 32 Àṣẹ Ẹ́sítà fìdí ọ̀rọ̀ nípa Púrímù+ múlẹ̀, wọ́n sì kọ ọ́ sínú ìwé kan.

10 Ọba Ahasuérúsì gbé iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún àwọn èèyàn tó ń gbé ilẹ̀ náà àti àwọn erékùṣù òkun.

2 Ní ti gbogbo ohun tó fi agbára àti okun rẹ̀ gbé ṣe, títí kan kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ipò gíga tí ọba gbé Módékáì+ sí,+ ǹjẹ́ wọn kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn àkókò+ àwọn ọba Mídíà àti Páṣíà?+ 3 Módékáì tó jẹ́ Júù ni igbá kejì Ọba Ahasuérúsì. Ẹni ńlá ni* láàárín àwọn Júù, gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ ló sì ń bọ̀wọ̀ fún un, ó ń ṣiṣẹ́ fún ire àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ń jà fún ire* gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn.

Wọ́n mọ̀ ọ́n sí Sásítà Kìíní, ọmọ Dáríúsì Ńlá (Dáríúsì Hisitápísì).

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “Kúṣì.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

Tàbí “Ohun èlò; Aago.”

Tàbí “kò sí ìkálọ́wọ́kò lórí.”

Tàbí “ààfin.”

Ní Héb., “ń mú ọkàn ọba yọ̀.”

Tàbí “ìránṣẹ́.”

Tàbí “láwàní.”

Tàbí “ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe nǹkan.” Ní Héb., “àwọn àkókò.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “ọ̀gá.”

Tàbí “ìránṣẹ́.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

Tàbí “ilé tí wọ́n kọ́ fún àwọn obìnrin.”

Tàbí “kí wọ́n máa wọ́ra fún wọn.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

Wọ́n pè é ní Jèhóákínì ní 2Ọb 24:8.

Tàbí “olùtọ́jú.”

Ó túmọ̀ sí “Òdòdó Mátílì.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

Tàbí “ààfin.”

Tàbí “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”

Tàbí “bí wọ́n á ṣe máa wọ́ra fún un.”

Tàbí “ilé tí wọ́n kọ́ fún àwọn obìnrin.”

Tàbí “ilé tí wọ́n kọ́ fún àwọn obìnrin.”

Tàbí “ìwọ́ra wọn.”

Tàbí “pẹ̀lú ìwọ́ra tí wọ́n máa ń ṣe fún àwọn obìnrin.”

Tàbí “láti ilé tí wọ́n kọ́ fún àwọn obìnrin.”

Tàbí “ilé kejì tí wọ́n kọ́ fún àwọn obìnrin.”

Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Wo Àfikún B15.

Tàbí “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”

Tàbí “láwàní.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “àwọn ọ̀dọ́bìnrin.”

Tàbí “jẹ́ òṣìṣẹ́ ààfin ọba.”

Ní Héb., “láti gbé ọwọ́ lé.”

Tàbí “bá Módékáì sọ ọ̀rọ̀ náà fún ọba.”

Ní Héb., “gbé ọwọ́ lé.”

Wo Àfikún B15.

Wo Àfikún B15.

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Tàbí kó jẹ́, “Màá san 10,000 tálẹ́ńtì sínú ibi ìṣúra ọba fún àwọn tó máa ṣe iṣẹ́ yìí.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

Tàbí “Súsà.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin.”

Tàbí “jẹ́.”

Tàbí “jẹ́.”

Nǹkan bíi mítà 22.3 (ẹsẹ̀ bàtà 73). Wo Àfikún B14.

Ní Héb., “oorun dá lójú ọba.”

Ní Héb., “láti gbé ọwọ́ lé.”

Tàbí “ìránṣẹ́.”

Tàbí “ààfin.”

Tàbí “ìránṣẹ́.”

Ní Héb., “látinú èso.”

Tàbí “jẹ́.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Nǹkan bíi mítà 22.3 (ẹsẹ̀ bàtà 73). Wo Àfikún B14.

Ní Héb., “ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí.”

Wo Àfikún B15.

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Wo Àfikún B15.

Tàbí “ẹ̀dà.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

Tàbí “òwú ọ̀gbọ̀.”

Tàbí “Súsà.”

Ní Héb., “ìmọ́lẹ̀.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Wo Àfikún B15.

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “ààfin.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Súsà.”

“Púrì” túmọ̀ sí “Kèké.” Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ tí wọ́n pè ní “Púrímù” ni wọ́n fi pe àjọyọ̀ àwọn Júù tí wọ́n ń ṣe ní oṣù kejìlá nínú kàlẹ́ńdà mímọ́. Wo Àfikún B15.

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Ó gbayì gan-an.”

Ní Héb., “ó ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà fún.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́