ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Ẹ́sírà 1:1-10:44
  • Ẹ́sírà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ́sírà
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́sírà

Ẹ́SÍRÀ

1 Ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Páṣíà, kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà+ sọ lè ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí Kírúsì ọba Páṣíà jí láti kéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì tún kọ ọ́ sílẹ̀+ pé:

2 “Ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà sọ nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé,+ ó sì pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù,+ tó wà ní Júdà. 3 Ta ni nínú yín tó jẹ́ èèyàn rẹ̀? Kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó lọ sí Jerúsálẹ́mù tó wà ní Júdà, kí ó sì tún ilé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kọ́, òun ni Ọlọ́run tòótọ́, tí ilé rẹ̀ wà ní Jerúsálẹ́mù.* 4 Àjèjì èyíkéyìí ní ilẹ̀ yìí,+ níbikíbi tó bá wà, kí àwọn aládùúgbò rẹ̀* ràn án lọ́wọ́, kí wọ́n fún un ní fàdákà àti wúrà, àwọn ẹrù àti àwọn ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá fún ilé Ọlọ́run tòótọ́+ tó wà ní Jerúsálẹ́mù.’”

5 Nígbà náà, àwọn olórí agbo ilé Júdà àti ti Bẹ́ńjámínì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn gbogbo ẹni tí Ọlọ́run tòótọ́ ta ẹ̀mí rẹ̀ jí, múra láti lọ tún ilé Jèhófà kọ́, èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù. 6 Gbogbo àwọn tó wà láyìíká wọn tì wọ́n lẹ́yìn,* wọ́n fún wọn ní àwọn nǹkan èlò fàdákà àti ti wúrà, àwọn ẹrù àti àwọn ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ṣeyebíye, yàtọ̀ sí gbogbo ọrẹ àtinúwá.

7 Ọba Kírúsì tún kó àwọn nǹkan èlò inú ilé Jèhófà jáde, àwọn tí Nebukadinésárì kó láti Jerúsálẹ́mù, tó sì kó sínú ilé ọlọ́run rẹ̀.+ 8 Kírúsì ọba Páṣíà kó wọn jáde lábẹ́ àbójútó Mítírédátì, ẹni tó ń tọ́jú ìṣúra, ó sì ka iye wọn fún Ṣẹṣibásà*+ ìjòyè Júdà.

9 Iye wọn nìyí: ọgbọ̀n (30) ohun èlò tó rí bí apẹ̀rẹ̀ tí wọ́n fi wúrà ṣe, ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ohun èlò tó rí bí apẹ̀rẹ̀ tí wọ́n fi fàdákà ṣe, ohun èlò mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) míì,* 10 ọgbọ̀n (30) abọ́ kékeré tí wọ́n fi wúrà ṣe, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́wàá (410) abọ́ kékeré tí wọ́n fi fàdákà ṣe àti ẹgbẹ̀rún kan (1,000) nǹkan èlò míì. 11 Gbogbo àwọn nǹkan èlò wúrà àti ti fàdákà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (5,400). Gbogbo nǹkan yìí ni Ṣẹṣibásà kó wá nígbà tí wọ́n kó àwọn tó wà nígbèkùn+ kúrò ní Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù.

2 Àwọn yìí ni àwọn èèyàn ìpínlẹ̀,* tí wọ́n pa dà lára àwọn tó wà nígbèkùn,+ àwọn tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kó lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì,+ àmọ́ tí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù àti Júdà nígbà tó yá, kálukú pa dà sí ìlú rẹ̀,+ 2 àwọn tí wọ́n tẹ̀ lé ni Serubábélì,+ Jéṣúà,+ Nehemáyà, Seráyà, Reeláyà, Módékáì, Bílíṣánì, Mísípárì, Bígífáì, Réhúmù àti Báánà.

Iye àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì nìyí:+ 3 àwọn ọmọ Páróṣì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé méjìléláàádọ́sàn-án (2,172); 4 àwọn ọmọ Ṣẹfatáyà jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìléláàádọ́rin (372); 5 àwọn ọmọ Áráhì+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé márùndínlọ́gọ́rin (775); 6 àwọn ọmọ Pahati-móábù,+ látinú àwọn ọmọ Jéṣúà àti Jóábù jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti méjìlá (2,812); 7 àwọn ọmọ Élámù+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254); 8 àwọn ọmọ Sátù+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé márùnlélógójì (945); 9 àwọn ọmọ Sákáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé ọgọ́ta (760); 10 àwọn ọmọ Bánì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìlélógójì (642); 11 àwọn ọmọ Bébáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́tàlélógún (623); 12 àwọn ọmọ Ásígádì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti méjìlélógún (1,222); 13 àwọn ọmọ Ádóníkámù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgọ́ta ó lé mẹ́fà (666); 14 àwọn ọmọ Bígífáì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (2,056); 15 àwọn ọmọ Ádínì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta (454); 16 àwọn ọmọ Átérì láti ilé Hẹsikáyà jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98); 17 àwọn ọmọ Bísáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́tàlélógún (323); 18 àwọn ọmọ Jórà jẹ́ méjìléláàádọ́fà (112); 19 àwọn ọmọ Háṣúmù+ jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún (223); 20 àwọn ọmọ Gíbárì jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn-ún (95); 21 àwọn ọmọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123); 22 àwọn ọkùnrin Nétófà jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56); 23 àwọn ọkùnrin Ánátótì+ jẹ́ méjìdínláàádóje (128); 24 àwọn ọmọ Ásímáfẹ́tì jẹ́ méjìlélógójì (42); 25 àwọn ọmọ Kiriati-jéárímù, Kéfírà àti Béérótì jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́tàlélógójì (743); 26 àwọn ọmọ Rámà+ àti Gébà+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mọ́kànlélógún (621); 27 àwọn ọkùnrin Míkímásì jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122); 28 àwọn ọkùnrin Bẹ́tẹ́lì àti Áì+ jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún (223); 29 àwọn ọmọ Nébò+ jẹ́ méjìléláàádọ́ta (52); 30 àwọn ọmọ Mágíbíṣì jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ (156); 31 àwọn ọmọ Élámù kejì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254); 32 àwọn ọmọ Hárímù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ogún (320); 33 àwọn ọmọ Lódì, Hádídì àti Ónò jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (725); 34 àwọn ọmọ Jẹ́ríkò jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé márùnlélógójì (345); 35 àwọn ọmọ Sénáà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgbọ̀n (3,630).

36 Àwọn àlùfáà nìyí:+ àwọn ọmọ Jedáyà+ láti ilé Jéṣúà+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́tàléláàádọ́rin (973); 37 àwọn ọmọ Ímérì+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé méjìléláàádọ́ta (1,052); 38 àwọn ọmọ Páṣúrì+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́tàdínláàádọ́ta (1,247); 39 àwọn ọmọ Hárímù+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé mẹ́tàdínlógún (1,017).

40 Àwọn ọmọ Léfì nìyí:+ àwọn ọmọ Jéṣúà àti Kádímíélì,+ látinú àwọn ọmọ Hodafáyà jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin (74). 41 Àwọn akọrin nìyí:+ àwọn ọmọ Ásáfù,+ wọ́n jẹ́ méjìdínláàádóje (128). 42 Àwọn ọmọ àwọn aṣọ́bodè nìyí:+ àwọn ọmọ Ṣálúmù, àwọn ọmọ Átérì, àwọn ọmọ Tálímónì,+ àwọn ọmọ Ákúbù,+ àwọn ọmọ Hátítà, àwọn ọmọ Ṣóbáì, gbogbo wọn lápapọ̀ jẹ́ mọ́kàndínlógóje (139).

43 Àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* nìyí:+ àwọn ọmọ Síhà, àwọn ọmọ Hásúfà, àwọn ọmọ Tábáótì, 44 àwọn ọmọ Kérósì, àwọn ọmọ Síáhà, àwọn ọmọ Pádónì, 45 àwọn ọmọ Lébánà, àwọn ọmọ Hágábà, àwọn ọmọ Ákúbù, 46 àwọn ọmọ Hágábù, àwọn ọmọ Sálímáì, àwọn ọmọ Hánánì, 47 àwọn ọmọ Gídélì, àwọn ọmọ Gáhárì, àwọn ọmọ Reáyà, 48 àwọn ọmọ Résínì, àwọn ọmọ Nékódà, àwọn ọmọ Gásámù, 49 àwọn ọmọ Úúsà, àwọn ọmọ Páséà, àwọn ọmọ Bésáì, 50 àwọn ọmọ Ásínà, àwọn ọmọ Méúnímù, àwọn ọmọ Néfúsímù, 51 àwọn ọmọ Bákíbúkì, àwọn ọmọ Hákúfà, àwọn ọmọ Háhúrì, 52 àwọn ọmọ Básílútù, àwọn ọmọ Méhídà, àwọn ọmọ Háṣà, 53 àwọn ọmọ Bákósì, àwọn ọmọ Sísérà, àwọn ọmọ Téémà, 54 àwọn ọmọ Nesáyà àti àwọn ọmọ Hátífà.

55 Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì nìyí: àwọn ọmọ Sótáì, àwọn ọmọ Sóférétì, àwọn ọmọ Pérúdà,+ 56 àwọn ọmọ Jálà, àwọn ọmọ Dákónì, àwọn ọmọ Gídélì, 57 àwọn ọmọ Ṣẹfatáyà, àwọn ọmọ Hátílì, àwọn ọmọ Pokereti-hásébáímù àti àwọn ọmọ Ámì.

58 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* àti ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé àádọ́rùn-ún àti méjì (392).

59 Àwọn tó lọ láti Tẹli-mélà, Tẹli-háṣà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, àmọ́ tí wọn kò lè sọ agbo ilé bàbá wọn àti ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀ wá láti fi hàn pé ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n nìyí:+ 60 àwọn ọmọ Deláyà, àwọn ọmọ Tòbáyà àti àwọn ọmọ Nékódà, wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìléláàádọ́ta (652). 61 Àwọn tó wá látinú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà nìyí: àwọn ọmọ Habáyà, àwọn ọmọ Hákósì,+ àwọn ọmọ Básíláì tó fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Básíláì+ ọmọ Gílíádì, tó sì wá ń jẹ́ orúkọ wọn. 62 Wọ́n wá àkọsílẹ̀ wọn láti mọ ìdílé tí wọ́n ti wá, àmọ́ wọn kò rí i, torí náà, wọn ò gbà kí wọ́n ṣiṣẹ́ àlùfáà.*+ 63 Gómìnà* sọ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ lára àwọn ohun mímọ́ jù lọ,+ títí wọ́n á fi rí àlùfáà tó máa bá wọn fi Úrímù àti Túmímù wádìí.+

64 Iye gbogbo ìjọ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ọgọ́ta (42,360),+ 65 yàtọ̀ sí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin wọn, tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mẹ́tàdínlógójì (7,337); wọ́n tún ní àwọn akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ igba (200). 66 Ẹṣin wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́rìndínlógójì (736), ìbaaka wọn jẹ́ igba ó lé márùnlélógójì (245), 67 ràkúnmí wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé márùndínlógójì (435), kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti ogún (6,720).

68 Nígbà tí wọ́n dé ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù, lára àwọn olórí agbo ilé ṣe ọrẹ àtinúwá+ fún ilé Ọlọ́run tòótọ́, kí wọ́n lè tún un kọ́* sí àyè rẹ̀.+ 69 Ohun tí wọ́n kó wá sí ibi ìṣúra iṣẹ́ ilé náà gẹ́gẹ́ bí agbára wọn ṣe tó ni, ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61,000) owó dírákímà* wúrà àti ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) mínà* fàdákà+ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún (100) aṣọ fún àwọn àlùfáà. 70 Àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn kan lára àwọn èèyàn náà, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́bodè pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* bẹ̀rẹ̀ sí í gbé inú àwọn ìlú wọn, gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì yòókù* sì ń gbé inú àwọn ìlú wọn.+

3 Nígbà tí oṣù keje+ pé, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, wọ́n kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan. 2 Jéṣúà+ ọmọ Jèhósádákì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ àlùfáà àti Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì+ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ dìde, wọ́n sì mọ pẹpẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè máa rú àwọn ẹbọ sísun lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè,+ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́.

3 Nítorí náà, wọ́n mọ pẹpẹ náà sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń bà wọ́n,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà lórí rẹ̀, àwọn ẹbọ sísun òwúrọ̀ àti ti ìrọ̀lẹ́.+ 4 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lákọsílẹ̀,+ ojoojúmọ́ ni wọ́n sì máa ń rú iye ẹbọ sísun tó yẹ kí wọ́n rú lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.+ 5 Lẹ́yìn èyí, wọ́n rú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo + àti ẹbọ tó wà fún àwọn òṣùpá tuntun+ àti àwọn tó wà fún gbogbo àsìkò àjọyọ̀ tí a yà sí mímọ́+ fún Jèhófà, títí kan àwọn ọrẹ àtinúwá tí ẹnì kọ̀ọ̀kan fínnúfíndọ̀ mú wá+ fún Jèhófà. 6 Láti ọjọ́ kìíní oṣù keje,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tíì fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀.

7 Wọ́n fún àwọn agékùúta+ àti àwọn oníṣẹ́ ọnà+ lówó, wọ́n tún kó oúnjẹ àti ohun mímu pẹ̀lú òróró fún àwọn ọmọ Sídónì àti àwọn ará Tírè, torí wọ́n kó gẹdú igi kédárì láti Lẹ́bánónì gba orí òkun wá sí Jópà,+ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Kírúsì ọba Páṣíà fún wọn.+

8 Ní ọdún kejì, lẹ́yìn tí wọ́n wá sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́ ní Jerúsálẹ́mù, ní oṣù kejì, Serubábélì ọmọ Ṣéálítíẹ́lì àti Jéṣúà ọmọ Jèhósádákì àti ìyókù àwọn arákùnrin wọn, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú gbogbo àwọn tó jáde wá sí Jerúsálẹ́mù láti ìgbèkùn+ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà; wọ́n yan àwọn ọmọ Léfì, láti ẹni ogún (20) ọdún sókè láti jẹ́ alábòójútó lórí iṣẹ́ ilé Jèhófà. 9 Torí náà, Jéṣúà àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Kádímíélì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Júdà, dara pọ̀ láti máa bójú tó àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, bákan náà, àwọn ọmọ Hénádádì+ àti àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, tí àwọn náà jẹ́ ọmọ Léfì dara pọ̀ mọ́ wọn.

10 Nígbà tí àwọn kọ́lékọ́lé fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀,+ àwọn àlùfáà wọ aṣọ iṣẹ́ wọn, wọ́n mú kàkàkí+ dání, àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn àwọn ọmọ Ásáfù mú síńbálì* dání, wọ́n dìde dúró láti yin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì fi lélẹ̀.+ 11 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn kọrin,+ wọ́n ń yin Jèhófà, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí Ísírẹ́lì sì wà títí láé.”+ Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn kígbe sókè láti yin Jèhófà nítorí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀. 12 Ọ̀pọ̀ lára àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú àwọn olórí agbo ilé, ìyẹn àwọn àgbààgbà tó mọ bí ilé náà ṣe rí tẹ́lẹ̀,+ sunkún kíkankíkan nígbà tí wọ́n rí i tí à ń fi ìpìlẹ̀ ilé yìí lélẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn míì sì ń kígbe ayọ̀ bí ohùn wọn ṣe ròkè tó.+ 13 Nítorí náà, àwọn èèyàn ò mọ ìyàtọ̀ nínú igbe ayọ̀ àti igbe ẹkún náà, torí igbe àwọn èèyàn náà ròkè débi pé àwọn tó wà ní ibi tó jìnnà réré ń gbọ́ igbe wọn.

4 Nígbà tí àwọn ọ̀tá Júdà àti Bẹ́ńjámínì + gbọ́ pé àwọn tó dé láti ìgbèkùn+ ń kọ́ tẹ́ńpìlì kan fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, 2 ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n lọ bá Serubábélì àti àwọn olórí agbo ilé, wọ́n sì sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká jọ kọ́ ilé yìí; nítorí Ọlọ́run yín làwa náà ń sìn,*+ òun la sì ń rúbọ sí láti ìgbà ayé Esari-hádónì+ ọba Ásíríà tó kó wa wá síbí.”+ 3 Àmọ́, Serubábélì àti Jéṣúà pẹ̀lú ìyókù àwọn olórí agbo ilé ní Ísírẹ́lì sọ fún wọn pé: “Kò sí ohun tó kàn yín nínú kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa,+ àwa nìkan ló máa kọ́ ọ fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Ọba Kírúsì tó jẹ́ ọba Páṣíà ṣe pàṣẹ fún wa.”+

4 Ni àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn èèyàn Júdà,* wọ́n sì ń mú kí ọkàn wọn domi, kí wọ́n má lè kọ́ ilé náà.+ 5 Wọ́n tìtorí wọn háyà àwọn agbani-nímọ̀ràn láti mú kí ìmọ̀ràn wọn já sófo+ ní gbogbo ọjọ́ Kírúsì ọba Páṣíà títí di ìgbà ìjọba Dáríúsì+ ọba Páṣíà. 6 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ahasuérúsì, wọ́n kọ̀wé ẹ̀sùn mọ́ àwọn tó ń gbé Júdà àti Jerúsálẹ́mù. 7 Nígbà ayé Atasásítà ọba Páṣíà, Bíṣílámù, Mítírédátì, Tábéélì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù kọ̀wé sí Ọba Atasásítà; wọ́n túmọ̀ lẹ́tà náà sí èdè Árámáíkì,+ ọ̀nà ìkọ̀wé èdè Árámáíkì ni wọ́n sì fi kọ ọ́.*

8 * Réhúmù olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin kọ lẹ́tà kan mọ́ Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí Ọba Atasásítà, lẹ́tà náà kà pé: 9 (Ó wá látọ̀dọ̀ Réhúmù olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù, àwọn adájọ́ àti àwọn gómìnà kéékèèké, àwọn akọ̀wé, àwọn èèyàn Érékì,+ àwọn ará Babilóníà, àwọn tó ń gbé ní Súsà,+ ìyẹn àwọn ọmọ Élámù+ 10 àti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí Ásénápárì ńlá àti ọlọ́lá kó lọ sí ìgbèkùn, tó sì ní kí wọ́n máa gbé ní àwọn ìlú Samáríà+ pẹ̀lú àwọn yòókù tó ń gbé ní agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò.* Ní báyìí, 11 ẹ̀dà lẹ́tà tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i nìyí.)

“Sí Ọba Atasásítà, látọ̀dọ̀ àwa ìránṣẹ́ rẹ, àwa tí a wà ní agbègbè Ìkọjá Odò: Ní báyìí, 12 a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé àwọn Júù tó wá látọ̀dọ̀ rẹ sí ọ̀dọ̀ wa níbí ti dé sí Jerúsálẹ́mù. Wọ́n ń kọ́ ìlú ọ̀tẹ̀ àti ìlú burúkú, wọ́n ti ń mọ àwọn ògiri rẹ̀,+ wọ́n sì ti ń tún àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ ṣe. 13 Kí ọba mọ̀ pé tí wọ́n bá tún ìlú náà kọ́, tí wọ́n sì parí àwọn ògiri rẹ̀, wọn ò ní san owó orí tàbí ìṣákọ́lẹ̀,*+ bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní san owó ibodè, èyí sì máa jẹ́ kí owó tó ń wọlé sí àpò ọba* dín kù. 14 Torí pé ààfin ni owó wa ti ń wá,* kò ní dáa ká rí ohun tó máa dènà àǹfààní ọba, ká má sì sọ, ìdí nìyẹn tí a fi kọ̀wé ránṣẹ́, kí ọba lè mọ̀, 15 kí o lè wádìí nínú àkọsílẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ.+ Wàá rí i nínú àkọsílẹ̀ pé ìlú yẹn jẹ́ ìlú ọ̀tẹ̀, ó máa ń pa àwọn ọba àti àwọn ìpínlẹ̀* lára, ó sì ti pẹ́ tí àwọn tó wà nínú rẹ̀ ti máa ń dìtẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pa ìlú náà run.+ 16 A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé, tí wọ́n bá tún ìlú yìí kọ́, tí wọ́n sì parí àwọn ògiri rẹ̀, o ò ní láṣẹ lórí* agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò.”+

17 Ọba wá ránṣẹ́ sí Réhúmù olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tó ń gbé ní Samáríà àti àwọn ibi yòókù ní agbègbè Ìkọjá Odò pé:

“Mo kí yín o! 18 Wọ́n ti fara balẹ̀ ka ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa* níwájú mi. 19 Mo ti pàṣẹ pé kí wọ́n wádìí, a sì rí i pé ó ti pẹ́ tí ìlú náà ti ń dìde sí àwọn ọba àti pé àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ máa ń ṣọ̀tẹ̀, wọ́n sì máa ń dìtẹ̀.+ 20 Àwọn ọba alágbára ti jẹ ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n ṣàkóso gbogbo agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò, àwọn èèyàn sì ń san owó orí, ìṣákọ́lẹ̀* àti owó ibodè fún wọn. 21 Ní báyìí, ẹ pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin yìí pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ dúró, kí wọ́n má bàa tún ìlú náà kọ́ títí màá fi pàṣẹ. 22 Ẹ rí i dájú pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ yìí falẹ̀, kí ìpalára tó ń fà fún ọba lè dáwọ́ dúró.”+

23 Lẹ́yìn tí wọ́n ka ẹ̀dà ìwé àṣẹ Ọba Atasásítà níwájú Réhúmù àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọ̀ àwọn Júù, wọ́n sì fipá dá wọn dúró. 24 Ìgbà náà ni iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù, dáwọ́ dúró; ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí di ọdún kejì ìjọba Dáríúsì ọba Páṣíà.+

5 Nígbà náà, wòlíì Hágáì+ àti wòlíì Sekaráyà+ ọmọ ọmọ Ídò+ sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn Júù tó wà ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù, ní orúkọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó ń darí wọn. 2 Ìgbà náà ni Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì àti Jéṣúà+ ọmọ Jèhósádákì bẹ̀rẹ̀ sí í tún ilé Ọlọ́run kọ́,+ èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù; àwọn wòlíì Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn, wọ́n sì ń tì wọ́n lẹ́yìn.+ 3 Ní àkókò yẹn, Táténáì gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò* àti Ṣetari-bósénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wá bá wọn, wọ́n sì bi wọ́n pé: “Ta ló fún yín láṣẹ láti kọ́ ilé yìí, kí ẹ sì parí iṣẹ́* rẹ̀?” 4 Wọ́n wá béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Kí lorúkọ àwọn ọkùnrin tó ń kọ́ ilé yìí?” 5 Àmọ́, ojú Ọlọ́run ò kúrò lára* àwọn àgbààgbà Júù,+ wọn ò sì dá wọn dúró títí wọ́n fi kọ̀wé ránṣẹ́ sí Dáríúsì, tí òun náà sì fi ìwé àṣẹ ránṣẹ́ pa dà lórí ọ̀rọ̀ náà.

6 Ẹ̀dà lẹ́tà tí Táténáì gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò àti Ṣetari-bósénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, àwọn gómìnà kéékèèké ní agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò, fi ránṣẹ́ sí Ọba Dáríúsì nìyí; 7 wọ́n fi ránṣẹ́ sí i, ohun tí wọ́n kọ nìyí:

“Sí Ọba Dáríúsì:

“Kí àlàáfíà wà pẹ̀lú rẹ! 8 A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a lọ sí ìpínlẹ̀* Júdà, ní ilé Ọlọ́run títóbi, wọ́n ń fi àwọn òkúta ńlá tí wọ́n ń yí sí àyè wọn kọ́ ilé náà, wọ́n sì ń to àwọn ẹ̀là gẹdú sí àwọn ògiri. Àwọn èèyàn náà ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ náà, ìsapá wọn sì ń mú kó tẹ̀ síwájú. 9 A béèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà wọn pé: ‘Ta ló fún yín láṣẹ láti kọ́ ilé yìí, kí ẹ sì parí iṣẹ́* rẹ̀?’+ 10 A tún béèrè orúkọ wọn lọ́wọ́ wọn ká lè sọ fún ọ, ká sì lè kọ orúkọ àwọn ọkùnrin tó jẹ́ olórí wọn.

11 “Èsì tí wọ́n fún wa nìyí: ‘Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, ilé tí wọ́n kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn là ń tún kọ́, èyí tí ọba ńlá kan ní Ísírẹ́lì kọ́, tó sì parí rẹ̀.+ 12 Àmọ́, nítorí pé àwọn baba wa múnú bí Ọlọ́run ọ̀run,+ ó fi wọ́n lé ọwọ́ Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì, ará Kálídíà tó wó ilé yìí lulẹ̀,+ tó sì kó àwọn èèyàn ibẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì.+ 13 Ṣùgbọ́n ní ọdún kìíní Kírúsì ọba Bábílónì, Ọba Kírúsì pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́.+ 14 Bákan náà, látinú tẹ́ńpìlì Bábílónì, Ọba Kírúsì kó àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà ilé Ọlọ́run jáde, èyí tí Nebukadinésárì kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ sí tẹ́ńpìlì Bábílónì.+ Ọba Kírúsì kó wọn fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ṣẹṣibásà,*+ ẹni tí Kírúsì fi ṣe gómìnà.+ 15 Kírúsì sọ fún un pé: “Kó àwọn ohun èlò yìí. Lọ kó wọn sínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀.”+ 16 Nígbà tí Ṣẹṣibásà yìí dé, ó fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run lélẹ̀,+ èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù; àtìgbà yẹn ni wọ́n sì ti ń kọ́ ilé náà títí di báyìí, àmọ́ wọn ò tíì parí rẹ̀.’+

17 “Ní báyìí, tó bá dáa lójú ọba, jẹ́ kí wọ́n yẹ inú ibi ìṣúra ọba wò ní Bábílónì, láti mọ̀ bóyá Ọba Kírúsì pàṣẹ pé kí wọ́n tún ilé Ọlọ́run yẹn kọ́ ní Jerúsálẹ́mù;+ kí ọba sì fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.”

6 Ìgbà náà ni Ọba Dáríúsì pa àṣẹ kan, wọ́n sì ṣe àyẹ̀wò nínú ibi ìkówèésí* tó wà ní àwọn ibi tí wọ́n ń kó ìṣúra sí ní Bábílónì. 2 Wọ́n rí àkájọ ìwé kan nínú ilé ńlá tó wà ní Ekibátánà, ní ìpínlẹ̀* Mídíà, ọ̀rọ̀ ìrántí tó wà nínú rẹ̀ nìyí:

3 “Ní ọdún kìíní Ọba Kírúsì, Ọba Kírúsì pa àṣẹ kan nípa ilé Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù, ó ní:+ ‘Ẹ tún ilé náà kọ́ kí ẹ lè máa rú àwọn ẹbọ níbẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ sí àyè rẹ̀; kí gíga rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,* kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,+ 4 kí ó ní ipele mẹ́ta òkúta ńlá tí wọ́n yí sí àyè wọn àti ipele kan ẹ̀là gẹdú;+ kí owó tí wọ́n máa fi ṣe é sì wá láti ilé ọba.+ 5 Bákan náà, kí a dá àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà ilé Ọlọ́run pa dà, èyí tí Nebukadinésárì kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì,+ kí wọ́n lè pa dà sí àyè wọn nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, kí a sì kó wọn sínú ilé Ọlọ́run.’+

6 “Nítorí náà, ìwọ Táténáì gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò* àti Ṣetari-bósénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ, ìyẹn àwọn gómìnà kéékèèké tó wà ní Ìkọjá Odò,+ ẹ má ṣe débẹ̀ o. 7 Ẹ má ṣe dí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yẹn lọ́wọ́. Gómìnà àwọn Júù àti àwọn àgbààgbà Júù yóò tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀. 8 Yàtọ̀ síyẹn, mo pàṣẹ ohun tí ẹ máa ṣe fún àwọn àgbààgbà Júù, kí wọ́n lè tún ilé Ọlọ́run kọ́, àṣẹ náà nìyí: Látinú ibi ìṣúra ọba,+ ìyẹn látinú owó orí tí ẹ gbà láti agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò ni kí ẹ ti máa fún àwọn ọkùnrin náà lówó tí wọ́n á fi ṣe iṣẹ́ náà, ẹ má sì fi falẹ̀, kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà lọ láìsí ìdíwọ́.+ 9 Ohunkóhun tí wọ́n bá nílò, látorí àwọn ọmọ akọ màlúù,+ àwọn àgbò+ àti àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn + fún àwọn ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, dórí àlìkámà,*+ iyọ̀,+ wáìnì+ àti òróró,+ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣe sọ, gbogbo rẹ̀ ni kí ẹ máa fún wọn lójoojúmọ́, kò gbọ́dọ̀ yẹ̀, 10 kí wọ́n lè máa mú ọrẹ tó ń mú inú Ọlọ́run ọ̀run dùn wá déédéé, kí wọ́n sì máa gbàdúrà fún ẹ̀mí ọba àti ti àwọn ọmọ rẹ̀.+ 11 Mo tún pa àṣẹ kan pé ẹnikẹ́ni tó bá rú òfin yìí, kí wọ́n yọ igi kan lára ilé rẹ̀, kí wọ́n gbé onítọ̀hún sókè, kí wọ́n dè é* mọ́ ọn, kí wọ́n sì sọ ilé rẹ̀ di ilé ìyàgbẹ́* gbogbo èèyàn nítorí ohun tó ṣe yìí. 12 Kí Ọlọ́run tó mú kí orúkọ rẹ̀ máa wà níbẹ̀+ gbá ọba tàbí èèyàn èyíkéyìí dà nù tí ó bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti rú òfin yìí, tí ó sì ba ilé Ọlọ́run yẹn jẹ́, èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Èmi, Dáríúsì ló pa àṣẹ yìí. Kí ẹ ṣe ohun tí mo sọ ní kánmọ́kánmọ́.”

13 Nígbà náà, Táténáì gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò àti Ṣetari-bósénáì+ pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, ṣe gbogbo ohun tí Ọba Dáríúsì pa láṣẹ ní kánmọ́kánmọ́. 14 Àwọn àgbààgbà Júù ń bá iṣẹ́ ìkọ́lé náà lọ, wọ́n ń tẹ̀ síwájú,+ àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Hágáì+ àti Sekaráyà+ ọmọ ọmọ Ídò sì ń fún wọn níṣìírí; wọ́n parí iṣẹ́ ìkọ́lé náà nípa àṣẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ àti nípa àṣẹ Kírúsì+ àti Dáríúsì+ àti Atasásítà+ ọba Páṣíà. 15 Wọ́n parí ilé náà ní ọjọ́ kẹta oṣù Ádárì,* ní ọdún kẹfà àkóso Ọba Dáríúsì.

16 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì  + pẹ̀lú àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀ fi ìdùnnú ṣe ayẹyẹ ṣíṣí* ilé Ọlọ́run yìí. 17 Ohun tí wọ́n mú wá fún ayẹyẹ ṣíṣí ilé Ọlọ́run yìí ni ọgọ́rùn-ún (100) akọ màlúù, igba (200) àgbò àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọ̀dọ́ àgùntàn, wọ́n sì tún mú akọ ewúrẹ́ méjìlá (12) wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye àwọn ẹ̀yà tó wà ní Ísírẹ́lì.+ 18 Wọ́n mú àwọn àlùfáà ní àwùjọ wọn àti àwọn ọmọ Léfì ní àwùjọ tí wọ́n pín wọn sí, wọ́n sì yàn wọ́n sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù,+ gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Mósè.+

19 Àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀ ṣe Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní.+ 20 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wẹ ara wọn mọ́,+ láìyọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, torí náà, gbogbo wọn ló wà ní mímọ́; wọ́n pa ẹran Ìrékọjá fún gbogbo àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀, fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ àlùfáà àti fún ara wọn. 21 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n dé láti ìgbèkùn jẹ nínú rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ẹni tó dara pọ̀ mọ́ wọn, tó ti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun àìmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ náà láti jọ́sìn* Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 22 Wọ́n tún fi ọjọ́ méje ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú+ tìdùnnú-tìdùnnú; nítorí Jèhófà ti mú kí wọ́n máa yọ̀, ó sì ti mú kí ọba Ásíríà ṣe ojú rere sí wọn,*+ tí ó fi tì wọ́n lẹ́yìn* lẹ́nu iṣẹ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

7 Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, nígbà ìjọba Atasásítà+ ọba Páṣíà, Ẹ́sírà*+ pa dà. Ẹ́sírà jẹ́ ọmọ Seráyà,+ ọmọ Asaráyà, ọmọ Hilikáyà,+ 2 ọmọ Ṣálúmù, ọmọ Sádókù, ọmọ Áhítúbù, 3 ọmọ Amaráyà, ọmọ Asaráyà,+ ọmọ Méráótì, 4 ọmọ Seraháyà, ọmọ Úsáì, ọmọ Búkì, 5 ọmọ Ábíṣúà, ọmọ Fíníhásì,+ ọmọ Élíásárì,+ ọmọ Áárónì+ olórí àlùfáà. 6 Ẹ́sírà yìí dé láti Bábílónì. Ó jẹ́ adàwékọ* tó mọ Òfin Mósè+ dunjú,* èyí tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Gbogbo ohun tó béèrè ni ọba fún un, nítorí ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà lára rẹ̀.

7 Àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn akọrin,+ àwọn aṣọ́bodè+ àti àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì*+ lọ sí Jerúsálẹ́mù ní ọdún keje Ọba Atasásítà. 8 Ẹ́sírà wá sí Jerúsálẹ́mù ní oṣù karùn-ún, ọdún keje ọba. 9 Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Bábílónì ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní, ó sì dé Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ kìíní oṣù karùn-ún, nítorí ọwọ́ rere Ọlọ́run rẹ̀ wà lára rẹ̀.+ 10 Ẹ́sírà ti múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀* láti wádìí nínú Òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́+ àti láti máa kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn ìlànà àti ìdájọ́ inú rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.+

11 Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Ọba Atasásítà fún Ẹ́sírà tó jẹ́ àlùfáà àti adàwékọ,* ọ̀jáfáfá nínú ẹ̀kọ́* àwọn àṣẹ Jèhófà àti àwọn ìlànà tó fún Ísírẹ́lì:

12 * “Atasásítà,+ ọba àwọn ọba, sí àlùfáà Ẹ́sírà, adàwékọ* Òfin Ọlọ́run ọ̀run: Kí àlàáfíà pípé máa jẹ́ tìrẹ. Ní báyìí, 13 mo ti pàṣẹ kan pé kí gbogbo ẹni tó wà lábẹ́ àkóso mi tó jẹ́ ara àwọn èèyàn Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà wọn àti àwọn ọmọ Léfì, tó bá fẹ́ bá ọ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí ó bá ọ lọ.+ 14 Nítorí ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ méje ló rán ọ láti wádìí bóyá wọ́n ń pa Òfin Ọlọ́run rẹ, tó wà pẹ̀lú* rẹ mọ́ ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù, 15 kí o sì kó fàdákà àti wúrà tí ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ fi ṣe ọrẹ àtinúwá fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù 16 pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí o bá gbà* ní gbogbo ìpínlẹ̀* Bábílónì àti ẹ̀bùn tí àwọn èèyàn náà àti àwọn àlùfáà fi ṣe ọrẹ àtinúwá fún ilé Ọlọ́run wọn, èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù.+ 17 Kí o tètè fi owó yìí ra àwọn akọ màlúù,+ àwọn àgbò+ àti àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn+ pẹ̀lú àwọn ohun tí wọ́n nílò fún ọrẹ ọkà+ àti ọrẹ ohun mímu,+ kí o sì fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ ilé Ọlọ́run yín, èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù.

18 “Ohun tó bá dára lójú rẹ àti lójú àwọn arákùnrin rẹ ni kí o fi ìyókù fàdákà àti wúrà náà ṣe, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run yín ṣe fẹ́. 19 Gbogbo ohun èlò tí wọ́n kó fún ọ fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run rẹ ni kí o fi jíṣẹ́ níwájú Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù.+ 20 Gbogbo ohun yòókù tí o bá nílò fún ilé Ọlọ́run rẹ, kí o gbà á láti ibi ìṣúra ọba.+

21 “Èmi Ọba Atasásítà ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn tó ń tọ́jú ìṣúra ní agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò* pé ohunkóhun tí àlùfáà Ẹ́sírà,+ adàwékọ* Òfin Ọlọ́run ọ̀run, bá béèrè lọ́wọ́ yín, kí ẹ fún un ní kánmọ́kánmọ́, 22 títí dórí ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì* fàdákà, ọgọ́rùn-ún (100) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* àlìkámà* àti ọgọ́rùn-ún (100) òṣùwọ̀n báàtì* wáìnì+ àti ọgọ́rùn-ún (100) òṣùwọ̀n báàtì òróró+ àti ìwọ̀n iyọ̀+ tí kò níye. 23 Gbogbo ohun tí Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè ni kí a fi ìtara ṣe fún ilé Ọlọ́run ọ̀run,+ kí ìbínú Ọlọ́run má bàa wá sórí ilẹ̀ tí ọba ń ṣàkóso àti sórí àwọn ọmọ ọba.+ 24 Bákan náà, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ gba owó orí, ìṣákọ́lẹ̀*+ tàbí owó ibodè lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tó jẹ́ àlùfáà, ọmọ Léfì, olórin,+ aṣọ́nà, ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì*+ tàbí òṣìṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run yìí.

25 “Ní tìrẹ, Ẹ́sírà, fi ọgbọ́n tí Ọlọ́run rẹ fún ọ* yan àwọn agbófinró àti àwọn onídàájọ́ tí wọ́n á máa ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn tó wà ní agbègbè Ìkọjá Odò, ìyẹn gbogbo àwọn tó mọ àwọn òfin Ọlọ́run rẹ; kí ẹ sì kọ́ ẹnikẹ́ni tí kò bá tíì mọ̀ wọ́n.+ 26 Gbogbo ẹni tí kò bá pa Òfin Ọlọ́run rẹ àti òfin ọba mọ́ ni kí wọ́n dá lẹ́jọ́ ní kánmọ́kánmọ́, ì báà jẹ́ ìdájọ́ ikú tàbí lílé kúrò láwùjọ tàbí owó ìtanràn tàbí ìfisẹ́wọ̀n.”

27 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ẹni tó fi sí ọba lọ́kàn láti ṣe ilé Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́ṣọ̀ọ́!+ 28 Ó ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi níwájú ọba+ àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀+ àti níwájú gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí wọ́n jẹ́ alágbára. Torí náà, mo mọ́kàn le* nítorí ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run mi wà lára mi, mo sì kó àwọn aṣáájú ọkùnrin* jọ látinú Ísírẹ́lì kí wọ́n lè bá mi lọ.

8 Àwọn olórí agbo ilé àti àkọsílẹ̀ orúkọ ìdílé àwọn tó tẹ̀ lé mi jáde kúrò ní Bábílónì nígbà ìjọba Ọba Atasásítà nìyí:+ 2 Gẹ́ṣómù, látinú àwọn ọmọ Fíníhásì;+ Dáníẹ́lì, látinú àwọn ọmọ Ítámárì;+ Hátúṣì, látinú àwọn ọmọ Dáfídì; 3 látinú àwọn ọmọ Ṣẹkanáyà àti látinú àwọn ọmọ Páróṣì, Sekaráyà, àádọ́jọ (150) ọkùnrin tí orúkọ wọn wà lákọsílẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 4 látinú àwọn ọmọ Pahati-móábù,+ Elieho-énáì ọmọ Seraháyà, igba (200) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 5 látinú àwọn ọmọ Sátù,+ Ṣẹkanáyà ọmọ Jáhásíẹ́lì, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 6 látinú àwọn ọmọ Ádínì,+ Ébédì ọmọ Jónátánì, àádọ́ta (50) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 7 látinú àwọn ọmọ Élámù,+ Jeṣáyà ọmọ Ataláyà, àádọ́rin (70) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 8 látinú àwọn ọmọ Ṣẹfatáyà,+ Sebadáyà ọmọ Máíkẹ́lì, ọgọ́rin (80) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 9 látinú àwọn ọmọ Jóábù, Ọbadáyà ọmọ Jéhíélì, igba ó lé méjìdínlógún (218) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 10 látinú àwọn ọmọ Bánì, Ṣẹ́lómítì ọmọ Josifáyà, ọgọ́jọ (160) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 11 látinú àwọn ọmọ Bébáì,+ Sekaráyà ọmọ Bébáì, ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n (28) sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 12 látinú àwọn ọmọ Ásígádì,+ Jóhánánì ọmọ Hákátánì, àádọ́fà (110) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 13 látinú àwọn ọmọ Ádóníkámù,+ àwọn tó kẹ́yìn, orúkọ wọn nìyí: Élífélétì, Jéélì àti Ṣemáyà, ọgọ́ta (60) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú wọn 14 àti látinú àwọn ọmọ Bígífáì,+ Útáì àti Sábúdì, àádọ́rin (70) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú wọn.

15 Mo kó wọn jọ níbi odò tó ṣàn wá sí Áháfà,+ a sì pàgọ́ síbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. Àmọ́ nígbà tí mo yẹ àwọn èèyàn náà àti àwọn àlùfáà wò, mi ò rí ìkankan lára àwọn ọmọ Léfì níbẹ̀. 16 Torí náà, mo ránṣẹ́ pe Élíésérì, Áríélì, Ṣemáyà, Élínátánì, Járíbù, Élínátánì, Nátánì, Sekaráyà àti Méṣúlámù, wọ́n jẹ́ aṣáájú ọkùnrin, mo tún ránṣẹ́ pe Jóyáríbù àti Élínátánì tí wọ́n jẹ́ olùkọ́. 17 Mo wá pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ bá Ídò tó jẹ́ olórí ní ibi tí wọ́n ń pè ní Kásífíà. Mo ní kí wọ́n sọ fún Ídò àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* tí wọ́n wà ní Kásífíà pé kí wọ́n bá wa mú àwọn òjíṣẹ́ wá fún ilé Ọlọ́run wa. 18 Nítorí pé ọwọ́ rere Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n mú ọlọ́gbọ́n ọkùnrin kan wá látinú àwọn ọmọ Máhílì+ ọmọ ọmọ Léfì ọmọ Ísírẹ́lì, orúkọ rẹ̀ ni Ṣerebáyà+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, gbogbo wọn jẹ́ méjìdínlógún (18); 19 wọ́n tún mú Haṣabáyà, Jeṣáyà látinú àwọn ọmọ Mérárì+ sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ wọn, gbogbo wọn jẹ́ ogún (20) ọkùnrin. 20 Igba ó lé ogún (220) lára àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* wà, tí orúkọ gbogbo wọn wà lákọsílẹ̀. Dáfídì àti àwọn ìjòyè ló ní kí àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì máa ran àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́.

21 Lẹ́yìn náà, mo kéde ààwẹ̀ níbi odò Áháfà, láti rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run wa àti láti wá ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìrìn àjò wa, fún àwa àti àwọn ọmọ wa àti fún gbogbo ẹrù wa. 22 Ó tì mí lójú láti ní kí ọba fún wa ní àwọn ọmọ ogun àti àwọn agẹṣin láti dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá lójú ọ̀nà, torí a ti sọ fún ọba pé: “Ọwọ́ rere Ọlọ́run wa wà lára gbogbo àwọn tó ń wá a,+ àmọ́ agbára rẹ̀ àti ìbínú rẹ̀ wà lórí gbogbo àwọn tó fi í sílẹ̀.”+ 23 Torí náà, a gbààwẹ̀, a sì bẹ Ọlọ́run wa pé kó tọ́ wa sọ́nà nínú ìrìn àjò yìí, ó sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.+

24 Mo wá ya àwọn méjìlá (12) sọ́tọ̀ lára àwọn olórí àlùfáà, àwọn ni, Ṣerebáyà àti Haṣabáyà+ pẹ̀lú mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn. 25 Lẹ́yìn náà, mo wọn fàdákà àti wúrà pẹ̀lú àwọn nǹkan èlò fún wọn, ọrẹ tí ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ mú wá fún ilé Ọlọ́run wa.+ 26 Nítorí náà, mo wọn ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé àádọ́ta (650) tálẹ́ńtì* fàdákà fún wọn àti ọgọ́rùn-ún (100) nǹkan èlò fàdákà tí ó tó tálẹ́ńtì méjì pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì wúrà 27 àti ogún (20) abọ́ kéékèèké tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ó tó ẹgbẹ̀rún kan (1,000) owó dáríkì* àti nǹkan èlò méjì tí wọ́n fi bàbà dáradára ṣe, tó ń pọ́n yòò, tí ó sì ṣeyebíye bíi wúrà.

28 Mo wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà,+ àwọn nǹkan èlò náà sì jẹ́ mímọ́, fàdákà àti wúrà náà jẹ́ ọrẹ àtinúwá fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín. 29 Ẹ tọ́jú wọn dáadáa títí ẹ ó fi wọ̀n wọ́n níwájú àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú àwọn olórí agbo ilé Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù,+ nínú àwọn yàrá* tó wà ní ilé Jèhófà.” 30 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì kó fàdákà àti wúrà pẹ̀lú àwọn nǹkan èlò tí mo wọ̀n fún wọn, kí wọ́n lè kó wọn wá sí ilé Ọlọ́run wa ní Jerúsálẹ́mù.

31 Níkẹyìn, a ṣí kúrò níbi odò Áháfà+ ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìíní+ láti lọ sí Jerúsálẹ́mù, ọwọ́ Ọlọ́run wa sì wà lára wa, ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá lójú ọ̀nà àti lọ́wọ́ àwọn dánàdánà. 32 Torí náà, a dé Jerúsálẹ́mù,+ a sì lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀. 33 Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn fàdákà àti wúrà àti àwọn nǹkan èlò nínú ilé Ọlọ́run wa,+ a sì kó wọn fún Mérémótì+ ọmọ àlùfáà Úríjà, Élíásárì ọmọ Fíníhásì sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àwọn ọmọ Léfì tó wà pẹ̀lú wọn ni Jósábádì+ ọmọ Jéṣúà àti Noadáyà ọmọ Bínúì.+ 34 Gbogbo nǹkan yìí ni wọ́n kà tí wọ́n sì wọ̀n, wọ́n sì kọ ìwọ̀n gbogbo wọn sílẹ̀. 35 Àwọn tó kúrò lóko ẹrú, ìyẹn àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀, rú àwọn ẹbọ sísun sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì, akọ màlúù+ méjìlá (12) fún gbogbo Ísírẹ́lì àti àgbò+ mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún (96) pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77) àti òbúkọ+ méjìlá (12) tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; gbogbo èyí jẹ́ ẹbọ sísun sí Jèhófà.+

36 Lẹ́yìn náà, a fún àwọn baálẹ̀* ọba àti àwọn gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò*+ ní ìwé àṣẹ ọba,+ wọ́n sì ti àwọn èèyàn náà àti ilé Ọlọ́run tòótọ́ lẹ́yìn.+

9 Gbàrà tí a parí àwọn nǹkan yìí, àwọn olórí wá bá mi, wọ́n sì sọ pé: “Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì kò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn àwọn ilẹ̀ tó yí wọn ká àti àwọn ohun ìríra wọn,+ ìyẹn àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn ará Jébúsì, àwọn ọmọ Ámónì, àwọn ọmọ Móábù, àwọn ará Íjíbítì+ àti àwọn Ámórì. + 2 Wọ́n ti fi lára àwọn ọmọbìnrin wọn ṣe aya, wọ́n sì tún fẹ́ wọn fún àwọn ọmọkùnrin wọn.+ Ní báyìí, àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ* mímọ́+ ti dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn àwọn ilẹ̀ tó yí wọn ká.+ Àwọn olórí àti àwọn alábòójútó sì ni òléwájú nínú ìwà àìṣòótọ́ yìí.”

3 Bí mo ṣe gbọ́ nípa nǹkan yìí, mo fa ẹ̀wù mi àti aṣọ àwọ̀lékè mi tí kò lápá ya, mo fa lára irun orí mi àti irùngbọ̀n mi tu, mo jókòó, kàyéfì ńlá sì ń ṣe mí. 4 Nígbà náà, gbogbo àwọn tó ní ọ̀wọ̀ fún* ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì kóra jọ sọ́dọ̀ mi nítorí ìwà àìṣòótọ́ àwọn tó dé láti ìgbèkùn, mo wà ní ìjókòó, kàyéfì ńlá sì ń ṣe mí títí di ìgbà ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́.+

5 Nígbà tí àkókò ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́+ tó, mo dìde nínú ìtìjú tó bá mi, tèmi ti ẹ̀wù mi àti aṣọ àwọ̀lékè mi tí kò lápá tó ti ya, mo kúnlẹ̀, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi sí Jèhófà Ọlọ́run mi. 6 Mo sọ pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi, ojú ń tì mí, ara sì ń tì mí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi, nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ti pọ̀ gan-an lórí wa, ẹ̀bi wa sì ti ga dé ọ̀run.+ 7 Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá wa ni ẹ̀bi wa ti pọ̀ gan-an títí di òní yìí;+ tìtorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ni o ṣe fi àwa, àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa lé àwọn ọba ilẹ̀ míì lọ́wọ́, tí wọ́n fi idà pa wá,+ tí wọ́n kó wa lọ sóko ẹrú,+ tí wọ́n kó ohun ìní wa,+ tí wọ́n sì dójú tì wá bó ṣe rí lónìí yìí.+ 8 Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa ti ṣojú rere sí wa fún ìgbà díẹ̀, o ti jẹ́ kí àwọn tó ṣẹ́ kù sá àsálà, o sì ti fún wa ní ibi ààbò* nínú ibi mímọ́ rẹ,+ láti mú kí ojú wa máa dán àti láti gbé wa dìde díẹ̀ nínú ipò ẹrú tí a wà, ìwọ Ọlọ́run wa. 9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹrú ni wá,+ Ọlọ́run wa kò fi wá sílẹ̀ nínú ipò ẹrú tí a wà; àmọ́ ó ti fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa níwájú àwọn ọba Páṣíà,+ láti gbé wa dìde kí a lè kọ́ ilé Ọlọ́run wa,+ kí a sì tún àwọn ibi tó ti di àwókù ṣe, kí ó sì fún wa ní odi ààbò* ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù.

10 “Lẹ́yìn gbogbo èyí, kí la tún fẹ́ sọ, ìwọ Ọlọ́run wa? Nítorí a ti pa àwọn àṣẹ rẹ tì, 11 èyí tí o fún wa nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wòlíì pé: ‘Ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà jẹ́ ilẹ̀ àìmọ́ nítorí ìwà àìmọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n fi kún ilẹ̀ náà láti ìpẹ̀kun kan dé èkejì nípasẹ̀ ìwà àìmọ́ wọn.+ 12 Torí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn, ẹ má sì gba àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín;+ ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun láti wá àlàáfíà tàbí aásìkí fún wọn,+ kí ẹ lè di alágbára, kí ẹ sì máa gbádùn àwọn ohun rere ilẹ̀ náà àti pé kí ẹ lè gbà á fún àwọn ọmọ yín títí láé.’ 13 Lẹ́yìn gbogbo ohun tó dé bá wa nítorí ìwà burúkú wa àti ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí a dá, ìwọ Ọlọ́run wa kò fi ìyà tó tọ́ sí wa jẹ wá nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ o sì ti jẹ́ kí àwa tí a wà níbí sá àsálà,+ 14 ǹjẹ́ ó yẹ ká tún máa tẹ àwọn àṣẹ rẹ lójú, ká sì máa bá àwọn èèyàn tó ń ṣe ohun ìríra dána?*+ Ṣé o kò ní bínú sí wa tí wàá fi pa wá run pátápátá tí ẹnì kankan kò fi ní ṣẹ́ kù tàbí yè bọ́? 15 Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, olódodo ni ọ́,+ nítorí àwa tí a yè bọ́ ti ṣẹ́ kù títí di òní yìí. Àwa rèé níwájú rẹ nínú ẹ̀bi wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tó ẹni tó lè dúró níwájú rẹ nítorí èyí.”+

10 Bí Ẹ́sírà ṣe ń gbàdúrà,+ tó sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́, tó ń sunkún, tó sì dojú bolẹ̀ níwájú ilé Ọlọ́run tòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin àti àwọn ọmọdé ní Ísírẹ́lì kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn èèyàn náà sì ń sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. 2 Ni Ṣẹkanáyà ọmọ Jéhíélì+ látinú àwọn ọmọ Élámù+ bá sọ fún Ẹ́sírà pé: “A ti hùwà àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa, bí a ṣe fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì* láàárín àwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wa ká.+ Síbẹ̀ náà, ìrètí ṣì wà fún Ísírẹ́lì. 3 Ní báyìí, jẹ́ ká bá Ọlọ́run wa dá májẹ̀mú+ pé a máa lé gbogbo àwọn aya náà lọ àti àwọn ọmọ tí wọ́n bí, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Jèhófà pa àti ohun tí àwọn tó ní ọ̀wọ̀* fún àṣẹ Ọlọ́run wa sọ.+ Ká ṣe ohun tí Òfin sọ. 4 Dìde, torí ìwọ lo ni iṣẹ́ yìí, a sì wà pẹ̀lú rẹ. Jẹ́ onígboyà, kí o sì gbé ìgbésẹ̀.”

5 Ni Ẹ́sírà bá dìde, ó sì ní kí àwọn tó jẹ́ olórí láàárín àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Ísírẹ́lì búra láti ṣe ohun tí wọ́n sọ.+ Torí náà, wọ́n búra. 6 Ẹ́sírà wá dìde kúrò níwájú ilé Ọlọ́run tòótọ́, ó sì lọ sínú yàrá* Jèhóhánánì ọmọ Élíáṣíbù nínú tẹ́ńpìlì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lọ síbẹ̀, kò jẹun, kò sì mu omi, torí ó ń ṣọ̀fọ̀ lórí ìwà àìṣòótọ́ àwọn tó dé láti ìgbèkùn.+

7 Lẹ́yìn náà, wọ́n kéde káàkiri Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé kí gbogbo àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀ kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù; 8 ẹnikẹ́ni tí kò bá sì wá láàárín ọjọ́ mẹ́ta, a ó gba* gbogbo ẹrù rẹ̀, a ó sì lé e kúrò ní àwùjọ àwọn tó dé láti ìgbèkùn, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu tí àwọn olórí àti àwọn àgbààgbà ṣe.+ 9 Nítorí náà, gbogbo àwọn èèyàn Júdà àti Bẹ́ńjámínì kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù láàárín ọjọ́ mẹ́ta, ìyẹn ní oṣù kẹsàn-án, ní ogúnjọ́ oṣù náà. Gbogbo àwọn èèyàn náà jókòó sí àgbàlá ilé Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń gbọ̀n nítorí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ àti nítorí òjò ńlá tó ń rọ̀.

10 Nígbà náà, àlùfáà Ẹ́sírà dìde, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ti hùwà àìṣòótọ́ bí ẹ ṣe lọ ń fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì,+ ẹ sì ti dá kún ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì. 11 Ní báyìí, ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí ó fẹ́. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn èèyàn ilẹ̀ náà àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn aya àjèjì.”+ 12 Gbogbo ìjọ náà wá dáhùn ní ohùn tó ròkè pé: “Ojúṣe wa ni láti ṣe ohun tí o sọ. 13 Àmọ́, àwọn èèyàn náà pọ̀, àsìkò òjò sì ni. Èèyàn ò lè dúró níta, ọ̀rọ̀ náà kì í sì í ṣe ohun tí a lè parí lọ́jọ́ kan tàbí méjì, nítorí a ti ṣọ̀tẹ̀ gan-an nínú ọ̀ràn yìí. 14 Ní báyìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí àwọn olórí wa ṣojú fún gbogbo ìjọ yìí;+ kí gbogbo àwọn tó wà nínú àwọn ìlú wa tí wọ́n ti fẹ́ àwọn aya àjèjì sì jáde wá ní àkókò tí a dá pẹ̀lú àwọn àgbààgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí a ó fi yí ìbínú Ọlọ́run wa tó ń jó bí iná kúrò lórí wa, nítorí ọ̀ràn yìí.”

15 Àmọ́, Jónátánì ọmọ Ásáhélì àti Jaseáyà ọmọ Tíkífà ta ko ọ̀rọ̀ yìí, Méṣúlámù àti Ṣábétáì+ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì sì tì wọ́n lẹ́yìn. 16 Ṣùgbọ́n àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀ ṣe ohun tí wọ́n fẹnu kò sí; àlùfáà Ẹ́sírà àti àwọn olórí ìdílé nínú àwọn agbo ilé bàbá wọn, tí orúkọ wọn wà lákọsílẹ̀, kóra jọ lọ́tọ̀ ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà; 17 nígbà tó di ọjọ́ kìíní oṣù kìíní, wọ́n yanjú ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn ọkùnrin tó fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì. 18 A sì wá rí i pé lára àwọn ọmọ àlùfáà ti fẹ́ àwọn aya àjèjì,+ àwọn ni: látinú àwọn ọmọ Jéṣúà+ ọmọ Jèhósádákì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, Maaseáyà, Élíésérì, Járíbù àti Gẹdaláyà. 19 Àmọ́, wọ́n ṣèlérí* pé àwọn máa lé àwọn aya wọn lọ, bákan náà, torí pé wọ́n jẹ̀bi, wọ́n máa fi àgbò kan látinú agbo ẹran rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+

20 Látinú àwọn ọmọ Ímérì,+ Hánáánì àti Sebadáyà; 21 látinú àwọn ọmọ Hárímù,+ Maaseáyà, Èlíjà, Ṣemáyà, Jéhíélì àti Ùsáyà; 22 látinú àwọn ọmọ Páṣúrì,+ Élíóénáì, Maaseáyà, Íṣímáẹ́lì, Nétánélì, Jósábádì àti Éléásà. 23 Látinú àwọn ọmọ Léfì, Jósábádì, Ṣíméì, Keláyà (ìyẹn, Kélítà), Petaháyà, Júdà àti Élíésérì; 24 látinú àwọn akọrin, Élíáṣíbù; látinú àwọn aṣọ́bodè, Ṣálúmù, Télémù àti Úráì.

25 Látinú Ísírẹ́lì, nínú àwọn ọmọ Páróṣì,+ Ramáyà, Isáyà, Málíkíjà, Míjámínì, Élíásárì, Málíkíjà àti Bẹnáyà; 26 látinú àwọn ọmọ Élámù,+ Matanáyà, Sekaráyà, Jéhíélì,+ Ábídì, Jérémótì àti Èlíjà; 27 látinú àwọn ọmọ Sátù,+ Élíóénáì, Élíáṣíbù, Matanáyà, Jérémótì, Sábádì àti Ásísà; 28 látinú àwọn ọmọ Bébáì,+ Jèhóhánánì, Hananáyà, Sábáì àti Átíláì; 29 látinú àwọn ọmọ Bánì, Méṣúlámù, Málúkù, Ádáyà, Jáṣúbù, Ṣéálì àti Jérémótì; 30 látinú àwọn ọmọ Pahati-móábù,+ Ádúnà, Kélálì, Bẹnáyà, Maaseáyà, Matanáyà, Bẹ́sálẹ́lì, Bínúì àti Mánásè; 31 látinú àwọn ọmọ Hárímù,+ Élíésérì, Isiṣíjà, Málíkíjà,+ Ṣemáyà, Ṣíméónì, 32 Bẹ́ńjámínì, Málúkù àti Ṣemaráyà; 33 látinú àwọn ọmọ Háṣúmù,+ Máténáì, Mátáátà, Sábádì, Élífélétì, Jérémáì, Mánásè àti Ṣíméì; 34 látinú àwọn ọmọ Bánì, Máádáì, Ámúrámù, Yúẹ́lì, 35 Bẹnáyà, Bedeáyà, Kélúhì, 36 Fanáyà, Mérémótì, Élíáṣíbù, 37 Matanáyà, Máténáì àti Jáásù; 38 látinú àwọn ọmọ Bínúì, Ṣíméì, 39 Ṣelemáyà, Nátánì, Ádáyà, 40 Makinádébáì, Ṣáṣáì, Ṣáráì, 41 Ásárẹ́lì, Ṣelemáyà, Ṣemaráyà, 42 Ṣálúmù, Amaráyà àti Jósẹ́fù; 43 látinú àwọn ọmọ Nébò, Jéélì, Matitáyà, Sábádì, Sébínà, Jádáì, Jóẹ́lì àti Bẹnáyà. 44 Gbogbo àwọn yìí ni wọ́n fẹ́ àwọn aya àjèjì,+ wọ́n sì lé àwọn aya wọn lọ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.+

Tàbí kó jẹ́, “ẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù.”

Ní Héb., “àwọn tó wà ní àyè rẹ̀.”

Ní Héb., “fún ọwọ́ wọn lókun.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Serubábélì tó wà ní Ẹsr 2:2; 3:8.

Tàbí “tó jẹ́ àfidípò.”

Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí agbègbè Bábílónì tàbí agbègbè Júdà.

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “Àwọn tí a fi fúnni.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Tàbí “wọ́n yọ wọ́n ní ipò àlùfáà torí wọ́n kà wọ́n sí aláìmọ́.”

Tàbí “Tíṣátà,” orúkọ oyè tí àwọn ará Páṣíà fún gómìnà ìpínlẹ̀.

Tàbí “mú kó dúró.”

Wọ́n gbà pé ó jẹ́ iye kan náà pẹ̀lú owó dáríkì wúrà ilẹ̀ Páṣíà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ gíráàmù 8.4. Kì í ṣe dírákímà inú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì. Wo Àfikún B14.

Mínà kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jẹ́ gíráàmù 570. Wo Àfikún B14.

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Ní Héb., “gbogbo Ísírẹ́lì.”

Tàbí “aro.”

Ní Héb., “ń wá.”

Ní Héb., “ń mú kí ọwọ́ àwọn èèyàn Júdà rọ.”

Tàbí kó jẹ́, “èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ ọ́, lẹ́yìn náà wọ́n túmọ̀ rẹ̀.”

Èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ Ẹsr 4:8 sí 6:18 ní ìbẹ̀rẹ̀.

Tàbí “Òdìkejì odò Yúfírétì.”

Tàbí “owó òde.”

Ní Árámáíkì, “àwọn ọba.”

Ní Árámáíkì, “iyọ̀ ààfin ni à ń jẹ.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Ní Árámáíkì, “ní ìpín kankan nínú.”

Tàbí kó jẹ́, “túmọ̀ ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa, wọ́n sì ti kà á.”

Tàbí “owó òde.”

Tàbí “Òdìkejì odò Yúfírétì.”

Tàbí “àwọn ìtì igi.”

Tàbí “Ọlọ́run ń ṣọ́.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “àwọn ìtì igi.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Serubábélì tó wà ní Ẹsr 2:2;; 3:8.

Ní Árámáíkì, “ilé àkọsílẹ̀.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Nǹkan bíi mítà 26.7 (ẹsẹ̀ bàtà 87.6) Wo Àfikún B14.

Tàbí “Òdìkejì odò Yúfírétì.”

Tàbí “wíìtì.”

Tàbí “kàn án.”

Tàbí kó jẹ́, “ààtàn; òkìtì ìgbẹ́.”

Wo Àfikún B15.

Tàbí “ìyàsímímọ́.”

Ní Héb., “wá.”

Ní Héb., “yí ọkàn ọba Ásíríà pa dà sọ́dọ̀ wọn.”

Ní Héb., “fún ọwọ́ wọn lókun.”

Ó túmọ̀ sí “Ìrànlọ́wọ́.”

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Tàbí “Ó jẹ́ ọ̀jáfáfá adàwékọ tó bá kan ti Òfin Mósè.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Tàbí “ti pinnu lọ́kàn rẹ̀.”

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Tàbí “ẹni tó ń ṣe àdàkọ ọ̀rọ̀.”

Èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ Ẹsr 7:12 sí 7:26 ní ìbẹ̀rẹ̀.

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Ní Árámáíkì, “ní ọwọ́.”

Ní Árámáíkì, “rí.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “Òdìkejì odò Yúfírétì.”

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Kọ́ọ̀ kan jẹ́ Lítà 220. Wo Àfikún B14.

Tàbí “wíìtì.”

Báàtì kan jẹ́ Lítà 22 (gálọ́ọ̀nù 5.81). Wo Àfikún B14.

Tàbí “owó òde.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Árámáíkì, “àwọn tí a fi fúnni.”

Ní Árámáíkì, “fi ọgbọ́n Ọlọ́run rẹ tó wà lọ́wọ́ rẹ.”

Tàbí “fún ara mi lókun.”

Ní Héb., “olórí.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Dáríkì jẹ́ owó ẹyọ wúrà ilẹ̀ Páṣíà. Wo Àfikún B14.

Tàbí “gbọ̀ngàn ìjẹun.”

Orúkọ oyè tó túmọ̀ sí “àwọn tó ń dáàbò bo ilẹ̀ tí ọba ń ṣàkóso,” àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ Ìjọba Ilẹ̀ Páṣíà ló ń tọ́ka sí níbí.

Tàbí “Òdìkejì odò Yúfírétì.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “tó bẹ̀rù.”

Ní Héb., “èèkàn kan.”

Ní Héb., “ògiri olókùúta.”

Tàbí “kí àwa àti àwọn tó ń ṣe ohun ìríra máa fẹ́ ara wa.”

Tàbí “mú àwọn obìnrin àjèjì wá sílé wa.”

Ní Héb., “ìbẹ̀rù.”

Tàbí “gbọ̀ngàn ìjẹun.”

Tàbí “fòfin de.”

Ní Héb., “wọ́n na ọwọ́ wọn.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́