DÁNÍẸ́LÌ
1 Ní ọdún kẹta àkóso Jèhóákímù+ ọba Júdà, Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì pàgọ́ tì í.+ 2 Nígbà tó yá, Jèhófà fi Jèhóákímù ọba Júdà lé e lọ́wọ́,+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò kan ní ilé* Ọlọ́run tòótọ́, ó sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Ṣínárì*+ sí ilé* ọlọ́run rẹ̀. Ó kó àwọn ohun èlò náà sínú ilé ìṣúra ọlọ́run rẹ̀.+
3 Ọba wá pàṣẹ fún Áṣípénásì olórí òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ pé kó mú lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* wá, títí kan àwọn ọmọ ọba àti ọmọ àwọn èèyàn pàtàkì.+ 4 Kí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́* tí kò ní àbùkù kankan, tí ìrísí wọn dáa, tí wọ́n ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye,+ tí wọ́n sì lè ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba. Kí ó kọ́ wọn ní èdè àwọn ará Kálídíà àti bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé. 5 Bákan náà, ọba ní kí wọ́n máa fún wọn ní oúnjẹ lójoojúmọ́, lára oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ àti lára wáìnì tó ń mu. Wọ́n máa fi ọdún mẹ́ta dá wọn lẹ́kọ̀ọ́,* tí ọdún náà bá sì ti pé, wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọba ṣiṣẹ́.
6 Àwọn kan wà lára wọn tí wọ́n wá látinú ẹ̀yà* Júdà: Dáníẹ́lì,*+ Hananáyà,* Míṣáẹ́lì* àti Asaráyà.*+ 7 Àgbà òṣìṣẹ́ láàfin sì fún wọn ní orúkọ;* ó pe Dáníẹ́lì ní Bẹtiṣásárì,+ ó pe Hananáyà ní Ṣádírákì, ó pe Míṣáẹ́lì ní Méṣákì, ó sì pe Asaráyà ní Àbẹ́dínígò.+
8 Àmọ́ Dáníẹ́lì pinnu lọ́kàn rẹ̀ pé òun ò ní fi oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ àti wáìnì tó ń mu sọ ara òun di aláìmọ́. Torí náà, ó ní kí àgbà òṣìṣẹ́ láàfin gba òun láyè kí òun má bàa fi àwọn nǹkan yìí sọ ara òun di aláìmọ́. 9 Ọlọ́run tòótọ́ sì mú kí àgbà òṣìṣẹ́ láàfin fi ojúure* àti àánú hàn sí Dáníẹ́lì.+ 10 Àmọ́ àgbà òṣìṣẹ́ láàfin sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ẹ̀rù olúwa mi ọba ń bà mí, ẹni tó ti ṣètò jíjẹ àti mímu yín. Tó bá wá rí i pé ìrísí yín burú ju ti àwọn ọ̀dọ́* yòókù tí ẹ jọ jẹ́ ojúgbà ńkọ́? Ẹ máa jẹ́ kí ọba dá mi* lẹ́bi.” 11 Àmọ́ Dáníẹ́lì sọ fún ẹni tí àgbà òṣìṣẹ́ láàfin yàn láti máa tọ́jú Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà pé: 12 “Jọ̀ọ́, fi ọjọ́ mẹ́wàá dán àwa ìránṣẹ́ rẹ wò, kí o máa fún wa ní nǹkan ọ̀gbìn jẹ, kí o sì máa fún wa ní omi mu; 13 kí o wá fi ìrísí wa wé ti àwọn ọ̀dọ́* tó ń jẹ oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ, lẹ́yìn náà, bí o bá ṣe rí àwa ìránṣẹ́ rẹ sí ni kí o ṣe sí wa.”
14 Ó wá gba ohun tí wọ́n sọ, ó sì fi ọjọ́ mẹ́wàá dán wọn wò. 15 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, ìrísí wọn dáa, ara wọn sì le* ju ti gbogbo àwọn ọ̀dọ́* tó ń jẹ oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ. 16 Torí náà, ẹni tó ń tọ́jú wọn máa ń gbé oúnjẹ aládùn wọn àti wáìnì wọn kúrò, ó sì máa ń fún wọn ní nǹkan ọ̀gbìn. 17 Ọlọ́run tòótọ́ fún àwọn ọ̀dọ́* mẹ́rin yìí ní ìmọ̀ àti òye nínú oríṣiríṣi ìkọ̀wé àti ọgbọ́n; ó sì fún Dáníẹ́lì ní òye láti túmọ̀ onírúurú ìran àti àlá.+
18 Nígbà tó tó àkókò tí ọba sọ pé kí wọ́n kó wọn wá,+ àgbà òṣìṣẹ́ láàfin kó wọn wá síwájú Nebukadinésárì. 19 Nígbà tí ọba bá wọn sọ̀rọ̀, kò sí ìkankan nínú wọn tó dà bíi Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà;+ wọ́n sì ń bá ọba ṣiṣẹ́. 20 Nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba bi wọ́n, tó gba ọgbọ́n àti òye, ó rí i pé wọ́n fi ìlọ́po mẹ́wàá dáa ju gbogbo àwọn àlùfáà onídán àti àwọn pidánpidán+ tó wà ní gbogbo ibi tó jọba lé lórí. 21 Dáníẹ́lì sì wà níbẹ̀ títí di ọdún àkọ́kọ́ Ọba Kírúsì.+
2 Ní ọdún kejì tí Nebukadinésárì di ọba, ó lá àwọn àlá kan, ọkàn* rẹ̀ ò sì balẹ̀ rárá+ débi pé kò rí oorun sùn. 2 Ọba wá pàṣẹ pé kí wọ́n pe àwọn àlùfáà onídán, àwọn pidánpidán, àwọn oṣó àti àwọn ará Kálídíà* láti rọ́ àwọn àlá ọba fún un. Torí náà, wọ́n wọlé, wọ́n sì dúró níwájú ọba.+ 3 Ọba wá sọ fún wọn pé: “Mo lá àlá kan, ọkàn* mi ò sì balẹ̀ torí mo fẹ́ mọ àlá tí mo lá.” 4 Àwọn ará Kálídíà fún ọba lésì ní èdè Árámáíkì+ pé:* “Kí ẹ̀mí ọba gùn títí láé. Rọ́ àlá náà fún àwa ìránṣẹ́ rẹ, a sì máa sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”
5 Ọba dá àwọn ará Kálídíà lóhùn pé: “Mi ò ní sọ jù báyìí lọ: Tí ẹ ò bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, a máa gé yín sí wẹ́wẹ́, a sì máa sọ ilé yín di ilé ìyàgbẹ́ gbogbo èèyàn.* 6 Àmọ́ tí ẹ bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, màá fún yín ní ẹ̀bùn, màá san yín lẹ́san, màá sì dá yín lọ́lá lọ́pọ̀lọpọ̀.+ Torí náà, ẹ sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.”
7 Wọ́n dáhùn lẹ́ẹ̀kejì pé: “Kí ọba rọ́ àlá náà fún àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, a sì máa sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”
8 Ọba fèsì pé: “Mo mọ̀ dáadáa pé ṣe lẹ kàn fẹ́ fi ọ̀rọ̀ yìí falẹ̀, torí ẹ mọ̀ pé ohun tí mo bá sọ ni abẹ gé. 9 Tí ẹ ò bá sọ àlá náà fún mi, ìyà kan náà ni màá fi jẹ gbogbo yín. Àmọ́ ẹ ti pinnu pé ẹ máa parọ́ fún mi, ẹ sì máa tàn mí jẹ títí dìgbà tí nǹkan fi máa yí pa dà. Torí náà, ẹ rọ́ àlá náà fún mi, màá sì mọ̀ pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”
10 Àwọn ará Kálídíà dá ọba lóhùn, wọ́n ní: “Kò sí ẹnì kankan ní ayé* tó lè ṣe ohun tí ọba ń béèrè, torí kò sí ọba ńlá tàbí gómìnà tó tíì béèrè irú rẹ̀ rí lọ́wọ́ àlùfáà onídán, pidánpidán tàbí ará Kálídíà kankan. 11 Àmọ́ ohun tí ọba ń béèrè ṣòro gan-an, kò sí ẹnì kankan tó lè sọ ọ́ fún ọba àfi àwọn ọlọ́run, tí kì í gbé láàárín àwọn ẹni kíkú.”*
12 Inú wá bí ọba gidigidi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo amòye Bábílónì run.+ 13 Lẹ́yìn tó pàṣẹ, tí wọ́n sì ti fẹ́ pa àwọn amòye náà, wọ́n wá Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà kí wọ́n lè pa wọ́n.
14 Ìgbà yẹn ni Dáníẹ́lì rọra fọgbọ́n bá Áríókù tó jẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ ọba sọ̀rọ̀, òun ló jáde lọ láti pa àwọn amòye Bábílónì. 15 Ó bi Áríókù, ẹni tó ń bá ọba ṣiṣẹ́ pé: “Kí ló dé tí ọba fi pa irú àṣẹ tó le tó báyìí?” Áríókù wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Dáníẹ́lì.+ 16 Torí náà, Dáníẹ́lì wọlé, ó sì ní kí ọba yọ̀ǹda àkókò fún òun kóun lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.
17 Dáníẹ́lì wá lọ sí ilé rẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà. 18 Ó ní kí wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run fún àánú nípa àṣírí yìí, kí wọ́n má bàa pa Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ run pẹ̀lú àwọn amòye Bábílónì yòókù.
19 Lẹ́yìn náà, a ṣí àṣírí náà payá fún Dáníẹ́lì nínú ìran lóru.+ Dáníẹ́lì sì yin Ọlọ́run ọ̀run. 20 Dáníẹ́lì sọ pé:
21 Ó ń yí ìgbà àti àsìkò pa dà,+
Ó ń mú ọba kúrò, ó sì ń fi ọba jẹ,+
Ó ń fún àwọn ọlọ́gbọ́n ní ọgbọ́n, ó sì ń fún àwọn tó ní òye ní ìmọ̀.+
22 Ó ń ṣí àwọn ohun tó jinlẹ̀ àti àwọn ohun tó pa mọ́ payá,+
Ó mọ ohun tó wà nínú òkùnkùn,+
Ìmọ́lẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+
23 Ìwọ Ọlọ́run àwọn baba ńlá mi, ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, tí mo sì ń fìyìn fún,
Torí o ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára.
O sì ti wá jẹ́ kí n mọ ohun tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ;
O ti jẹ́ ká mọ ohun tó ń da ọba láàmú.”+
24 Dáníẹ́lì wá wọlé lọ bá Áríókù, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Bábílónì run,+ ó sì sọ fún un pé: “Má pa ìkankan nínú àwọn amòye Bábílónì. Mú mi wọlé lọ síwájú ọba, màá sì sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.”
25 Áríókù yára mú Dáníẹ́lì wọlé síwájú ọba, ó sì sọ fún un pé: “Mo ti rí ọkùnrin kan lára àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn ní Júdà,+ tó lè sọ ìtumọ̀ náà fún ọba.” 26 Ọba sọ fún Dáníẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹtiṣásárì+ pé: “Ṣé lóòótọ́ lo lè rọ́ àlá tí mo lá fún mi, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀?”+ 27 Dáníẹ́lì dá ọba lóhùn pé: “Ìkankan nínú àwọn amòye, àwọn pidánpidán, àwọn àlùfáà onídán àti àwọn awòràwọ̀ ò lè sọ àṣírí tí ọba ń béèrè fún un.+ 28 Àmọ́ Ọlọ́run kan wà ní ọ̀run, tó jẹ́ Ẹni tó ń ṣí àwọn àṣírí payá,+ ó sì ti jẹ́ kí Ọba Nebukadinésárì mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́. Àlá rẹ nìyí, àwọn ìran tí o sì rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ nìyí:
29 “Ní tìrẹ, ọba, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ló wá sí ọ lọ́kàn lórí ibùsùn rẹ, Ẹni tó ń ṣí àwọn àṣírí payá sì ti jẹ́ kí o mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀. 30 Ní tèmi, kì í ṣe torí pé mo gbọ́n ju ẹnikẹ́ni tó wà láàyè ni a ṣe ṣí àṣírí yìí payá fún mi; àmọ́ ó jẹ́ torí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá náà, kí o lè mọ èrò tó wá sí ọ lọ́kàn.+
31 “Ìwọ ọba ń wò, o sì rí ère ńlá kan. Ère yẹn tóbi, ó sì ń tàn yòò, ó dúró níwájú rẹ, ìrísí rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù gidigidi. 32 Wúrà tó dáa ni orí ère yẹn,+ fàdákà ni igẹ̀ àti apá rẹ̀,+ bàbà sì ni ikùn àti itan rẹ̀,+ 33 irin ni ẹsẹ̀ rẹ̀,+ apá kan irin àti apá kan amọ̀* sì ni àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.+ 34 Ò ń wò títí a fi gé òkúta kan jáde, tó jẹ́ pé ọwọ́ kọ́ ló gé e, ó kọ lu ère náà ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ tó jẹ́ irin àti amọ̀, ó sì fọ́ ọ túútúú.+ 35 Ìgbà yẹn ni gbogbo irin, amọ̀, bàbà, fàdákà àti wúrà fọ́ túútúú, ó sì dà bí ìyàngbò* láti ibi ìpakà ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, atẹ́gùn sì gbé wọn lọ títí kò fi ṣẹ́ ku nǹkan kan. Àmọ́ òkúta tó kọ lu ère náà di òkè ńlá, ó sì bo gbogbo ayé.
36 “Àlá náà nìyí, a sì máa sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. 37 Ìwọ ọba, ọba àwọn ọba, tí Ọlọ́run ọ̀run ti fún ní ìjọba,+ agbára, okun àti ògo, 38 tó sì ti fi àwọn èèyàn lé lọ́wọ́, ibi yòówù kí wọ́n máa gbé, títí kan àwọn ẹranko orí ilẹ̀ àtàwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, tó sì fi ṣe ọba lórí gbogbo wọn,+ ìwọ fúnra rẹ ni orí wúrà náà.+
39 “Àmọ́ ìjọba míì máa dìde lẹ́yìn rẹ,+ tí kò tó ọ; lẹ́yìn èyí ni ìjọba míì, ìkẹta, tó jẹ́ bàbà, tó máa ṣàkóso gbogbo ayé.+
40 “Ní ti ìjọba kẹrin, ó máa le bí irin.+ Torí bí irin ṣe ń fọ́ gbogbo nǹkan míì túútúú, tó sì ń lọ̀ ọ́, àní, bí irin ṣe ń rún nǹkan wómúwómú, ó máa fọ́ gbogbo èyí túútúú, ó sì máa rún un wómúwómú.+
41 “Bí o sì ṣe rí i pé àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ jẹ́ apá kan amọ̀ ti amọ̀kòkò àti apá kan irin, ìjọba náà máa pínyà, àmọ́ ó ṣì máa le bí irin lápá kan, bí o ṣe rí i pé irin náà dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírọ̀. 42 Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ sì ṣe jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba náà ṣe máa lágbára lápá kan, tí kò sì ní lágbára lápá kan. 43 Bí o ṣe rí i tí irin dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírọ̀, wọ́n máa dà pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn;* àmọ́ wọn ò ní lẹ̀ mọ́ra, ọ̀kan mọ́ ìkejì, bí irin àti amọ̀ ò ṣe lè lẹ̀ mọ́ra.
44 “Ní ọjọ́ àwọn ọba yẹn, Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀,+ tí kò ní pa run láé.+ A ò ní gbé ìjọba yìí fún èèyàn èyíkéyìí míì.+ Ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú,+ ó máa fòpin sí gbogbo wọn, òun nìkan ló sì máa dúró títí láé,+ 45 bí o ṣe rí i tí òkúta kan gé kúrò lára òkè náà, tó jẹ́ pé ọwọ́ kọ́ ló gé e, tó sì fọ́ irin, bàbà, amọ̀, fàdákà àti wúrà túútúú.+ Ọlọ́run Atóbilọ́lá ti jẹ́ kí ọba mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.+ Òótọ́ ni àlá náà, ìtumọ̀ rẹ̀ sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.”
46 Ọba Nebukadinésárì wá dojú bolẹ̀ níwájú Dáníẹ́lì, ó sì júbà rẹ̀. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un lẹ́bùn, kí wọ́n sì sun tùràrí fún un. 47 Ọba sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Lóòótọ́, Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba ni Ọlọ́run yín, ó sì jẹ́ Ẹni tó ń ṣí àwọn àṣírí payá, torí pé o rí àṣírí yìí ṣí payá.”+ 48 Ọba wá gbé Dáníẹ́lì ga, ó fún un ní ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn tó dáa, ó sì fi ṣe alákòóso lórí gbogbo ìpínlẹ̀* Bábílónì+ àti olórí àwọn aṣíwájú gbogbo amòye Bábílónì. 49 Bí Dáníẹ́lì sì ṣe béèrè, ọba yan Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò+ láti máa bójú tó ìpínlẹ̀* Bábílónì, àmọ́ Dáníẹ́lì ń ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba.
3 Ọba Nebukadinésárì ṣe ère wúrà kan, gíga rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,* fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà.* Ó gbé e kalẹ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà ní ìpínlẹ̀* Bábílónì. 2 Ọba Nebukadinésárì wá ránṣẹ́ sí àwọn baálẹ̀, àwọn aṣíwájú, àwọn gómìnà, àwọn agbani-nímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn adájọ́, àwọn agbófinró àti gbogbo àwọn alábòójútó ìpínlẹ̀* pé kí wọ́n kóra jọ, kí wọ́n wá síbi ayẹyẹ tí wọ́n fẹ́ fi ṣí ère tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀.
3 Torí náà, àwọn baálẹ̀, àwọn aṣíwájú, àwọn gómìnà, àwọn agbani-nímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn adájọ́, àwọn agbófinró àti gbogbo àwọn alábòójútó ìpínlẹ̀* kóra jọ síbi ayẹyẹ tí wọ́n fẹ́ fi ṣí ère tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀. Wọ́n sì dúró síwájú ère tí Nebukadinésárì gbé kalẹ̀. 4 Ẹni tó ń kéde wá kígbe pé: “A pàṣẹ fún ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà, 5 pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn púpọ̀, háàpù onígun mẹ́ta, ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo ohun ìkọrin míì, kí ẹ wólẹ̀, kí ẹ sì jọ́sìn ère wúrà tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀. 6 Ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kó sì jọ́sìn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la máa jù ú sínú iná ìléru tó ń jó.”+ 7 Torí náà, nígbà tí gbogbo èèyàn gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn púpọ̀, háàpù onígun mẹ́ta, ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti gbogbo ohun ìkọrin míì, gbogbo èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn ère wúrà tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀.
8 Ìgbà yẹn ni àwọn ará Kálídíà kan wá síwájú, wọ́n sì fẹ̀sùn* kan àwọn Júù. 9 Wọ́n sọ fún Ọba Nebukadinésárì pé: “Kí ẹ̀mí ọba gùn títí láé. 10 Ìwọ ọba lo pàṣẹ pé tí gbogbo èèyàn bá ti gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn púpọ̀, háàpù onígun mẹ́ta, ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo ohun ìkọrin míì, kí wọ́n wólẹ̀, kí wọ́n sì jọ́sìn ère wúrà náà; 11 àti pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kó sì jọ́sìn, a máa jù ú sínú iná ìléru tó ń jó.+ 12 Àmọ́ àwọn Júù kan wà tí o yàn pé kí wọ́n máa bójú tó ìpínlẹ̀* Bábílónì, ìyẹn Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò.+ Àwọn ọkùnrin yìí ò kà ọ́ sí rárá, ọba. Wọn ò sin àwọn ọlọ́run rẹ, wọ́n sì kọ̀ láti jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”
13 Inú wá bí Nebukadinésárì gidigidi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò wá. Torí náà, wọ́n mú àwọn ọkùnrin yìí wá síwájú ọba. 14 Nebukadinésárì sọ fún wọn pé: “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ṣé òótọ́ ni pé ẹ ò sin àwọn ọlọ́run mi,+ ẹ sì kọ̀ láti jọ́sìn ère wúrà tí mo gbé kalẹ̀? 15 Ní báyìí, tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn púpọ̀, háàpù onígun mẹ́ta, ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo ohun ìkọrin míì, ohun tó máa dáa ni pé kí ẹ ṣe tán láti wólẹ̀, kí ẹ sì jọ́sìn ère tí mo ṣe. Àmọ́ tí ẹ bá kọ̀ láti jọ́sìn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n máa jù yín sínú iná ìléru tó ń jó. Ta sì ni ọlọ́run tó lè gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ mi?”+
16 Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò dá ọba lóhùn pé: “Nebukadinésárì, kò sídìí láti ṣàlàyé ohunkóhun fún ọ lórí ọ̀rọ̀ yìí. 17 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ọba, Ọlọ́run wa tí à ń sìn lè gbà wá sílẹ̀ kúrò nínú iná ìléru tó ń jó, ó sì lè gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ.+ 18 Àmọ́ tí kò bá tiẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ pé a ò ní sin àwọn ọlọ́run rẹ, a ò sì ní jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”+
19 Inú wá bí Nebukadinésárì gan-an sí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò débi pé ojú rẹ̀ yí pa dà sí wọn,* ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú kí iná ìléru náà gbóná ní ìlọ́po méje ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. 20 Ó sọ fún àwọn kan lára àwọn alágbára ọkùnrin tó wà nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé kí wọ́n de Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, kí wọ́n sì jù wọ́n sínú iná ìléru tó ń jó.
21 Wọ́n wá de àwọn ọkùnrin yìí tàwọn ti aṣọ ìlékè tí wọ́n wọ̀, ẹ̀wù, fìlà àti gbogbo aṣọ ọrùn wọn, wọ́n sì jù wọ́n sínú iná ìléru tó ń jó. 22 Torí pé àṣẹ ọba le gan-an, iná ìléru náà sì gbóná kọjá ààlà, ọwọ́ iná náà pa àwọn ọkùnrin tó mú Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò lọ. 23 Àmọ́ àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ṣubú sínú iná ìléru tó ń jó náà ní dídè.
24 Jìnnìjìnnì wá bo Ọba Nebukadinésárì, ó yára dìde, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè rẹ̀ pé: “Ṣebí ọkùnrin mẹ́ta la dè, tí a sì jù sínú iná?” Wọ́n dá ọba lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ọba.” 25 Ó sọ pé: “Ẹ wò ó! Ọkùnrin mẹ́rin ni mò ń rí tí wọ́n ń rìn fàlàlà ní àárín iná náà, ohunkóhun ò ṣe wọ́n, ẹni kẹrin sì rí bí ọmọ àwọn ọlọ́run.”
26 Nebukadinésárì wá sún mọ́ ilẹ̀kùn iná ìléru tó ń jó náà, ó sì sọ pé: “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,+ ẹ jáde, kí ẹ sì máa bọ̀!” Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò sì jáde láti àárín iná náà. 27 Àwọn baálẹ̀, àwọn aṣíwájú, àwọn gómìnà àti àwọn ìjòyè ọba tí wọ́n pé jọ síbẹ̀+ rí i pé iná náà ò pa àwọn ọkùnrin yìí lára* rárá;+ iná ò ra ẹyọ kan lára irun orí wọn, aṣọ ìlékè wọn ò yí pa dà, wọn ò tiẹ̀ gbóòórùn iná lára wọn.
28 Nebukadinésárì wá kéde pé: “Ẹ yin Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò,+ tó rán áńgẹ́lì rẹ̀, tó sì gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e, wọ́n sì kọ̀ láti tẹ̀ lé àṣẹ ọba, wọ́n ṣe tán láti kú* dípò kí wọ́n sin ọlọ́run míì yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn tàbí kí wọ́n jọ́sìn rẹ̀.+ 29 Torí náà, mo pa á láṣẹ pé èèyàn èyíkéyìí, orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà tó bá sọ ohunkóhun tí kò dáa sí Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ṣe la máa gé e sí wẹ́wẹ́, a sì máa sọ ilé rẹ̀ di ilé ìyàgbẹ́ gbogbo èèyàn;* torí kò sí ọlọ́run míì tó lè gbani là bí èyí.”+
30 Ọba wá gbé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ga* ní ìpínlẹ̀* Bábílónì.+
4 “Ọba Nebukadinésárì kéde fún gbogbo èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà tó ń gbé ní gbogbo ayé pé: Kí àlàáfíà yín pọ̀ sí i! 2 Inú mi dùn láti kéde àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run Gíga Jù Lọ ti ṣe fún mi. 3 Ẹ wo bí àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ ṣe tóbi tó àti bí àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ṣe lágbára tó! Ìjọba tó wà títí láé ni ìjọba rẹ̀, àkóso rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.+
4 “Èmi Nebukadinésárì wà nínú ilé mi, ọkàn mi balẹ̀, nǹkan sì ń lọ dáadáa fún mi ní ààfin mi. 5 Mo lá àlá kan tó dẹ́rù bà mí. Bí mo ṣe dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn mi, àwọn àwòrán àti ìran tí mo rí dáyà já mi.+ 6 Mo wá pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn amòye Bábílónì wá síwájú mi, kí wọ́n lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi.+
7 “Ìgbà yẹn ni àwọn àlùfáà onídán, àwọn pidánpidán, àwọn ará Kálídíà* àti àwọn awòràwọ̀+ wọlé wá. Nígbà tí mo rọ́ àlá náà fún wọn, wọn ò lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.+ 8 Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Dáníẹ́lì wá síwájú mi, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹtiṣásárì,+ látinú orúkọ ọlọ́run mi,+ ẹni tí ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ + wà nínú rẹ̀, mo sì rọ́ àlá náà fún un:
9 “‘Bẹtiṣásárì, olórí àwọn àlùfáà onídán,+ ó dá mi lójú pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ,+ kò sì sí àṣírí kankan tó le jù fún ọ.+ Torí náà, ṣàlàyé ìran tí mo rí lójú àlá mi fún mi àti ohun tó túmọ̀ sí.
10 “‘Nínú ìran tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan+ ní àárín ayé, igi náà sì ga fíofío.+ 11 Igi náà dàgbà, ó sì lágbára, orí rẹ̀ kan ọ̀run, a sì lè rí i láti gbogbo ìkángun ayé. 12 Àwọn ewé rẹ̀ rẹwà, èso rẹ̀ pọ̀ yanturu, oúnjẹ sì wà lórí rẹ̀ fún gbogbo ayé. Àwọn ẹranko orí ilẹ̀ ń wá ibòji wá sábẹ́ rẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ń gbé lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀, gbogbo ohun alààyè* sì ń rí oúnjẹ jẹ lára rẹ̀.
13 “‘Bí mo ṣe ń wo ìran tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí olùṣọ́ kan, ẹni mímọ́, tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run.+ 14 Ó ké jáde pé: “Ẹ gé igi náà lulẹ̀,+ ẹ gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, ẹ gbọn àwọn ewé rẹ̀ dà nù, kí ẹ sì tú àwọn èso rẹ̀ ká! Kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì kúrò lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀. 15 Àmọ́ ẹ fi kùkùté igi náà sílẹ̀ pẹ̀lú gbòǹgbò rẹ̀* nínú ilẹ̀, kí ẹ sì fi ọ̀já irin àti bàbà dè é láàárín koríko pápá. Ẹ jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i, kí ìpín rẹ̀ sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko láàárín ewéko ayé.+ 16 Kí ọkàn rẹ̀ yí pa dà kúrò ní ti èèyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, kí ìgbà méje+ sì kọjá lórí rẹ̀.+ 17 Àṣẹ tí àwọn olùṣọ́+ pa nìyí, àwọn ẹni mímọ́ ló sì béèrè fún un, kí àwọn èèyàn tó wà láàyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé,+ ẹni tó bá wù ú ló ń gbé e fún, ẹni tó sì rẹlẹ̀ jù nínú àwọn èèyàn ló ń fi síbẹ̀.”
18 “‘Àlá tí èmi, Ọba Nebukadinésárì lá nìyí; ó yá, ìwọ Bẹtiṣásárì, sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, torí gbogbo àwọn amòye yòókù nínú ìjọba mi kò lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.+ Àmọ́ ìwọ lè sọ ọ́, torí pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ.’
19 “Ní àkókò yẹn, ẹnu ya Dáníẹ́lì fúngbà díẹ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹtiṣásárì,+ èrò ọkàn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ́rù bà á.
“Ọba sọ pé, ‘Bẹtiṣásárì, má ṣe jẹ́ kí àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ dẹ́rù bà ọ́.’
“Bẹtiṣásárì dáhùn pé, ‘Olúwa mi, kí àlá náà ṣẹ sí àwọn tó kórìíra rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì ṣẹ sí àwọn ọ̀tá rẹ lára.
20 “‘Igi tí o rí, tó di ńlá, tó sì lágbára, tí orí rẹ̀ kan ọ̀run, tí gbogbo ayé sì ń rí i,+ 21 tí àwọn ewé rẹ̀ rẹwà, tí èso rẹ̀ pọ̀ yanturu, tó sì jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ayé, tí àwọn ẹranko orí ilẹ̀ ń gbé lábẹ́ rẹ̀, tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀,+ 22 ọba, ìwọ ni, torí pé o ti di ẹni ńlá, o sì ti di alágbára, títóbi rẹ ti dé ọ̀run,+ àkóso rẹ sì ti dé àwọn ìkángun ayé.+
23 “‘Ọba wá rí olùṣọ́ kan, ẹni mímọ́,+ tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó ń sọ pé: “Ẹ gé igi náà lulẹ̀, kí ẹ sì pa á run, àmọ́ ẹ fi kùkùté igi náà sílẹ̀ pẹ̀lú gbòǹgbò rẹ̀* nínú ilẹ̀, kí ẹ sì fi ọ̀já irin àti bàbà dè é láàárín koríko pápá. Ẹ jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i, kí ìpín rẹ̀ sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko títí ìgbà méje fi máa kọjá lórí rẹ̀.”+ 24 Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí, ọba; àṣẹ tí Ẹni Gíga Jù Lọ pa, tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ sí olúwa mi ọba ni. 25 Wọ́n máa lé ọ kúrò láàárín àwọn èèyàn, ọ̀dọ̀ àwọn ẹranko ni wàá máa gbé, a sì máa fún ọ ní ewéko jẹ bí akọ màlúù; ìrì ọ̀run máa sẹ̀ sí ọ lára,+ ìgbà méje + sì máa kọjá lórí rẹ,+ títí o fi máa mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tó bá sì wù ú ló ń gbé e fún.+
26 “‘Àmọ́ torí wọ́n sọ pé kí wọ́n fi kùkùté igi náà sílẹ̀ pẹ̀lú gbòǹgbò rẹ̀,*+ ìjọba rẹ máa pa dà di tìrẹ lẹ́yìn tí o bá mọ̀ pé ọ̀run ló ń ṣàkóso. 27 Torí náà, ọba, kí ìmọ̀ràn mi rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ. Yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nípa ṣíṣe ohun tó tọ́, kí o sì yí pa dà kúrò nínú ìwà burúkú rẹ nípa fífi àánú hàn sí àwọn aláìní. Ó ṣeé ṣe kí nǹkan túbọ̀ lọ dáadáa fún ọ.’”+
28 Gbogbo nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí Ọba Nebukadinésárì.
29 Lẹ́yìn oṣù méjìlá (12), ó ń rìn lórí òrùlé ààfin ọba Bábílónì. 30 Ọba ń sọ pé: “Ṣebí Bábílónì Ńlá nìyí, tí mo fi agbára mi àti okun mi kọ́ fún ilé ọba àti fún ògo ọlá ńlá mi?”
31 Ọba ò tíì sọ̀rọ̀ yìí tán lẹ́nu tí ohùn kan fi dún láti ọ̀run pé: “À ń sọ fún ìwọ Ọba Nebukadinésárì pé, ‘Ìjọba náà ti kúrò lọ́wọ́ rẹ,+ 32 wọ́n sì máa lé ọ kúrò láàárín àwọn èèyàn. Ọ̀dọ̀ àwọn ẹranko ni wàá máa gbé, a máa fún ọ ní ewéko jẹ bí akọ màlúù, ìgbà méje sì máa kọjá lórí rẹ, títí o fi máa mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tó bá sì wù ú ló ń gbé e fún.’”+
33 Ní ìṣẹ́jú yẹn, ọ̀rọ̀ náà ṣẹ sí Nebukadinésárì lára. Wọ́n lé e kúrò láàárín àwọn èèyàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ewéko bí akọ màlúù, ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i lára, títí irun rẹ̀ fi gùn bí ìyẹ́ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dà bí èékánná ẹyẹ.+
34 “Ní òpin àkókò yẹn,+ èmi Nebukadinésárì gbójú sókè ọ̀run, òye mi sì pa dà sínú mi; mo yin Ẹni Gíga Jù Lọ, mo sì fi ìyìn àti ògo fún Ẹni tó wà láàyè títí láé, torí àkóso tó wà títí láé ni àkóso rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.+ 35 Kò ka gbogbo àwọn tó ń gbé ayé sí nǹkan kan, ohun tó bá sì wù ú ló ń ṣe láàárín àwọn ọmọ ogun ọ̀run àti àwọn tó ń gbé ayé. Kò sí ẹni tó lè dá a dúró*+ tàbí kó sọ fún un pé, ‘Kí lo ṣe yìí?’+
36 “Ìgbà yẹn ni òye mi pa dà sínú mi, ògo ìjọba mi, ọlá ńlá mi àti iyì mi sì pa dà sára mi.+ Àwọn ìjòyè mi àtàwọn èèyàn pàtàkì wá mi kàn, a sì dá mi pa dà sórí ìjọba mi, mo sì túbọ̀ di ẹni ńlá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
37 “Ní báyìí, èmi Nebukadinésárì ń yin Ọba ọ̀run,+ mò ń gbé e ga, mo sì ń fi ògo fún un, torí òtítọ́ ni gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, ọ̀nà rẹ̀ tọ́,+ ó sì lè rẹ àwọn tó ń gbéra ga wálẹ̀.”+
5 Ní ti Ọba Bẹliṣásárì,+ ó se àsè ńlá kan fún ẹgbẹ̀rún (1,000) àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì, ó sì ń mu wáìnì níwájú wọn.+ 2 Nígbà tí wáìnì ń pa Bẹliṣásárì, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà tí Nebukadinésárì bàbá rẹ̀ kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù wá,+ kí ọba àti àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì, àwọn wáhàrì* rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ onípò kejì lè fi wọ́n mutí. 3 Wọ́n wá kó àwọn ohun èlò wúrà tí wọ́n kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì ilé Ọlọ́run tó wà ní Jerúsálẹ́mù wá, ọba àti àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì, àwọn wáhàrì* rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ onípò kejì sì fi wọ́n mutí. 4 Wọ́n mu wáìnì, wọ́n sì yin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi wúrà, fàdákà, bàbà, irin, igi àti òkúta ṣe.
5 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn ìka ọwọ́ èèyàn fara hàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ̀wé síbi tí wọ́n rẹ́ lára ògiri ààfin ọba níwájú ọ̀pá fìtílà, ọba sì ń rí ẹ̀yìn ọwọ́ náà bó ṣe ń kọ̀wé. 6 Ara ọba wá funfun,* èrò ọkàn rẹ̀ sì kó jìnnìjìnnì bá a, ìgbáròkó rẹ̀ mì,+ àwọn orúnkún rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbá ara wọn.
7 Ọba ké jáde pé kí wọ́n ránṣẹ́ pe àwọn pidánpidán, àwọn ará Kálídíà* àti àwọn awòràwọ̀.+ Ọba sọ fún àwọn amòye Bábílónì pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ka ọ̀rọ̀ yìí, tó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, a máa fi aṣọ aláwọ̀ pọ́pù wọ̀ ọ́, a máa fi ìlẹ̀kẹ̀ wúrà sí i lọ́rùn,+ ó sì máa di igbá kẹta nínú ìjọba.”+
8 Gbogbo àwọn amòye ọba wá wọlé, àmọ́ wọn ò lè ka ọ̀rọ̀ náà, wọn ò sì lè sọ ohun tó túmọ̀ sí fún ọba.+ 9 Torí náà, ẹ̀rù ba Ọba Bẹliṣásárì gidigidi, ojú rẹ̀ sì funfun; ọ̀rọ̀ náà sì rú àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì lójú.+
10 Torí ohun tí ọba àti àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì sọ, ayaba wọnú gbọ̀ngàn tí wọ́n ti ń jẹ àsè. Ayaba sọ pé: “Kí ẹ̀mí ọba gùn títí láé. Má ṣe jẹ́ kí èrò rẹ kó jìnnìjìnnì bá ọ, má sì jẹ́ kí ojú rẹ funfun. 11 Ọkùnrin kan* wà nínú ìjọba rẹ tó ní ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́. Nígbà ayé bàbá rẹ, ó ní ìmọ̀, ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n, bí ọgbọ́n àwọn ọlọ́run.+ Ọba Nebukadinésárì, bàbá rẹ fi ṣe olórí àwọn àlùfáà onídán, àwọn pidánpidán, àwọn ará Kálídíà* àti àwọn awòràwọ̀;+ ohun tí bàbá rẹ ṣe nìyí, ọba. 12 Torí Dáníẹ́lì, ẹni tí ọba pè ní Bẹtiṣásárì,+ ní ẹ̀mí tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye láti túmọ̀ àwọn àlá, láti ṣàlàyé àwọn àlọ́, kó sì wá ojútùú sí ohun tó bá lọ́jú pọ̀.*+ Jẹ́ kí wọ́n pe Dáníẹ́lì wá, ó sì máa sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”
13 Wọ́n wá mú Dáníẹ́lì wá síwájú ọba. Ọba bi Dáníẹ́lì pé: “Ṣé ìwọ ni Dáníẹ́lì, tí wọ́n mú nígbèkùn ní Júdà,+ tí bàbá mi ọba mú wá láti Júdà?+ 14 Mo ti gbọ́ nípa rẹ pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run wà nínú rẹ,+ o sì ní ìmọ̀, ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n tó ṣàrà ọ̀tọ̀.+ 15 Wọ́n mú àwọn amòye àti àwọn pidánpidán wá síwájú mi, kí wọ́n lè ka ọ̀rọ̀ yìí, kí wọ́n sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, àmọ́ wọn ò lè sọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí.+ 16 Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé o lè sọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀,+ o sì lè wá ojútùú sí ohun tó bá lọ́jú pọ̀.* Tí o bá lè ka ọ̀rọ̀ yìí, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, a máa fi aṣọ aláwọ̀ pọ́pù wọ̀ ọ́, a máa fi ìlẹ̀kẹ̀ wúrà sí ọ lọ́rùn, o sì máa di igbá kẹta nínú ìjọba.”+
17 Dáníẹ́lì wá dá ọba lóhùn pé: “Di àwọn ẹ̀bùn rẹ mú, kí o sì fi ta àwọn míì lọ́rẹ. Àmọ́ màá ka ọ̀rọ̀ náà fún ọba, màá sì sọ ohun tó túmọ̀ sí fún un. 18 Ní tìrẹ, ọba, Ọlọ́run Gíga Jù Lọ gbé ìjọba fún Nebukadinésárì bàbá rẹ, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó sì fún un ní ògo àti ọlá ńlá.+ 19 Torí pé Ó jẹ́ kó di ẹni ńlá, gbogbo èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà ń gbọ̀n rìrì níwájú rẹ̀.+ Ó lè pa ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ tàbí kó dá a sí, ó sì lè gbé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ga tàbí kó rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀.+ 20 Àmọ́ nígbà tí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, tí ẹ̀mí rẹ̀ sì le, débi tó fi kọjá àyè rẹ̀,+ a rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀ látorí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, a sì gba iyì rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀. 21 A lé e kúrò láàárín aráyé, a jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ dà bíi ti ẹranko, ó sì ń gbé pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó. A fún un ní ewéko jẹ bí akọ màlúù, ìrì ọ̀run sì sẹ̀ sí i lára, títí ó fi mọ̀ pé Ọlọ́run Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tó bá sì wù ú ló ń gbé e fún.+
22 “Àmọ́ ìwọ Bẹliṣásárì ọmọ rẹ̀, o ò rẹ ara rẹ sílẹ̀, bí o tiẹ̀ mọ gbogbo èyí. 23 Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe lo gbé ara rẹ ga sí Olúwa ọ̀run,+ o sì ní kí wọ́n kó àwọn ohun èlò ilé rẹ̀ wá fún ọ.+ Ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ pàtàkì, àwọn wáhàrì rẹ àti àwọn ìyàwó rẹ onípò kejì wá fi wọ́n mu wáìnì, ẹ sì ń yin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi fàdákà, wúrà, bàbà, irin, igi àti òkúta ṣe, àwọn ọlọ́run tí kò rí nǹkan kan, tí wọn ò gbọ́ nǹkan kan, tí wọn ò sì mọ nǹkan kan.+ Àmọ́ o ò yin Ọlọ́run tí èémí rẹ+ àti gbogbo ọ̀nà rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀. 24 Torí náà, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ọwọ́ náà ti wá, tó sì kọ ọ̀rọ̀ yìí.+ 25 Ohun tó kọ nìyí: MÉNÈ, MÉNÈ, TÉKÉLÍ àti PÁRÁSÍNÌ.
26 “Ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí nìyí: MÉNÈ, Ọlọ́run ti ka iye ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti fòpin sí i.+
27 “TÉKÉLÌ, a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o ò kúnjú ìwọ̀n.
28 “PÉRÉSÌ, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mídíà àti Páṣíà.”+
29 Bẹliṣásárì wá pàṣẹ, wọ́n sì fi aṣọ aláwọ̀ pọ́pù wọ Dáníẹ́lì, wọ́n fi ìlẹ̀kẹ̀ wúrà sí i lọ́rùn; wọ́n sì kéde pé ó máa di igbá kẹta nínú ìjọba.+
30 Òru ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n pa Bẹliṣásárì, ọba àwọn ará Kálídíà.+ 31 Dáríúsì + ará Mídíà sì gba ìjọba; ọjọ́ orí rẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ọdún méjìlélọ́gọ́ta (62).
6 Ó dáa lójú Dáríúsì kó fi ọgọ́fà (120) baálẹ̀ jẹ lórí gbogbo ìjọba náà.+ 2 Ó fi ìjòyè mẹ́ta ṣe olórí wọn, Dáníẹ́lì+ jẹ́ ọ̀kan lára wọn; àwọn baálẹ̀+ náà á máa jábọ̀ fún wọn, kí ọba má bàa pàdánù ohunkóhun. 3 Dáníẹ́lì sì ń fi hàn pé òun yàtọ̀ sí àwọn ìjòyè yòókù àtàwọn baálẹ̀, torí ẹ̀mí tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wà nínú rẹ̀,+ ọba sì ń gbèrò láti gbé e ga lórí gbogbo ìjọba náà.
4 Ìgbà yẹn ni àwọn ìjòyè àtàwọn baálẹ̀ ń wá ọ̀nà láti fẹ̀sùn kan Dáníẹ́lì lórí ọ̀rọ̀ ìjọba,* àmọ́ wọn ò rí ohunkóhun tó lè mú kí wọ́n fẹ̀sùn kàn án, wọn ò sì rí ìwà ìbàjẹ́ kankan, torí ó ṣeé fọkàn tán, kì í fiṣẹ́ ṣeré, kò sì hùwà ìbàjẹ́ rárá. 5 Àwọn ọkùnrin yìí wá sọ pé: “A ò lè rí ohunkóhun tí a máa fi fẹ̀sùn kan Dáníẹ́lì yìí, àfi tí a bá fi òfin Ọlọ́run rẹ̀ mú un.”+
6 Àwọn ìjòyè àtàwọn baálẹ̀ yìí wá jọ lọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ọba Dáríúsì, kí ẹ̀mí rẹ gùn títí láé. 7 Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba, àwọn aṣíwájú, àwọn baálẹ̀, àwọn olóyè jàǹkàn-jàǹkàn àti àwọn gómìnà ti gbìmọ̀ pọ̀ láti fi àṣẹ kan lélẹ̀ látọ̀dọ̀ ọba, kí wọ́n sì kà á léèwọ̀* pé, láàárín ọgbọ̀n (30) ọjọ́, ẹnikẹ́ni tó bá béèrè nǹkan lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí èèyàn èyíkéyìí yàtọ̀ sí ìwọ ọba, ká ju onítọ̀hún sínú ihò kìnnìún.+ 8 Ní báyìí, ọba, gbé àṣẹ náà kalẹ̀, kí o sì fọwọ́ sí i,+ kó má ṣeé yí pa dà, gẹ́gẹ́ bí òfin àwọn ará Mídíà àti Páṣíà, tí kò ṣeé fagi lé.”+
9 Torí náà, Ọba Dáríúsì fọwọ́ sí àṣẹ náà àti ìfòfindè náà.
10 Àmọ́, gbàrà tí Dáníẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti fọwọ́ sí àṣẹ náà, ó lọ sínú ilé rẹ̀, èyí tí yàrá orí òrùlé rẹ̀ ní fèrèsé* tó ṣí sílẹ̀, tó kọjú sí ọ̀nà Jerúsálẹ́mù.+ Ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́ ló máa ń kúnlẹ̀ láti gbàdúrà, tó sì ń yin Ọlọ́run rẹ̀, bó ṣe máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà ṣáájú àkókò yìí. 11 Ìgbà yẹn ni àwọn ọkùnrin náà já wọlé, wọ́n sì rí i tí Dáníẹ́lì ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó sì ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣojúure sí òun.
12 Wọ́n wá lọ bá ọba, wọ́n sì rán ọba létí òfin tó ṣe, wọ́n ní: “Ṣebí o fọwọ́ sí òfin tó sọ pé, ẹnikẹ́ni tó bá béèrè nǹkan lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí èèyàn èyíkéyìí yàtọ̀ sí ìwọ ọba láàárín ọgbọ̀n (30) ọjọ́, ńṣe ni ká ju onítọ̀hún sínú ihò kìnnìún?” Ọba fèsì pé: “Òfin náà ò yí pa dà, gẹ́gẹ́ bí òfin àwọn ará Mídíà àti Páṣíà, tí kò ṣeé fagi lé.”+ 13 Wọ́n sọ fún ọba lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Dáníẹ́lì, ọ̀kan lára àwọn ìgbèkùn Júdà,+ kò ka ìwọ ọba sí, kò sì ka òfin tí o fọwọ́ sí sí, àmọ́ ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́ ló ń gbàdúrà.”+ 14 Gbàrà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìdààmú bá a gidigidi, ó wá ń ro bí òun ṣe lè gba Dáníẹ́lì sílẹ̀; títí ilẹ̀ fi ṣú, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti gbà á sílẹ̀. 15 Níkẹyìn, àwọn ọkùnrin yẹn jọ lọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì sọ fún ọba pé: “Ọba, rántí pé òfin àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ni pé ìfòfindè tàbí àṣẹ èyíkéyìí tí ọba bá gbé kalẹ̀ kò ṣeé yí pa dà.”+
16 Torí náà, ọba pàṣẹ, wọ́n wá mú Dáníẹ́lì wá, wọ́n sì jù ú sínú ihò kìnnìún.+ Ọba sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ọlọ́run rẹ tí ò ń fi ìgbà gbogbo sìn máa gbà ọ́ sílẹ̀.” 17 Wọ́n wá gbé òkúta kan wá, wọ́n sì fi dí ẹnu ihò náà, ọba sì fi òrùka àṣẹ rẹ̀ àti òrùka àṣẹ àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì gbé èdìdì lé e, kí wọ́n má bàa yí ohunkóhun pa dà lórí ọ̀rọ̀ Dáníẹ́lì.
18 Ọba lọ sí ààfin rẹ̀. Ó gbààwẹ̀ mọ́jú, kò gbà kí wọ́n dá òun lára yá,* kò sì rí oorun sùn.* 19 Níkẹyìn, gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, ọba dìde, ó sì yára lọ síbi ihò kìnnìún náà. 20 Bó ṣe ń sún mọ́ ihò náà, ó fi ohùn ìbànújẹ́ ké pe Dáníẹ́lì. Ọba bi Dáníẹ́lì pé: “Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, ṣé Ọlọ́run rẹ tí ò ń fi ìgbà gbogbo sìn gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kìnnìún?” 21 Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Dáníẹ́lì sọ fún ọba pé: “Ìwọ ọba, kí ẹ̀mí rẹ gùn títí láé. 22 Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún náà lẹ́nu,+ wọn ò sì ṣe mí léṣe,+ torí ó rí i pé mi ò mọwọ́ mẹsẹ̀; mi ò sì ṣe ohun burúkú kankan sí ìwọ ọba.”
23 Inú ọba dùn gan-an, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n gbé Dáníẹ́lì jáde kúrò nínú ihò náà. Nígbà tí wọ́n gbé Dáníẹ́lì jáde kúrò nínú ihò náà, kò fara pa rárá, torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀.+
24 Ọba wá pàṣẹ, wọ́n mú àwọn ọkùnrin tó fẹ̀sùn* kan Dáníẹ́lì wá, wọ́n sì jù wọ́n sínú ihò kìnnìún, pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn àtàwọn ìyàwó wọn. Àmọ́, wọn ò tíì dé ìsàlẹ̀ ihò náà tí àwọn kìnnìún náà fi bò wọ́n, wọ́n sì fọ́ gbogbo egungun wọn túútúú.+
25 Ọba Dáríúsì wá kọ̀wé sí gbogbo èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà tó ń gbé ní gbogbo ayé pé:+ “Kí àlàáfíà yín pọ̀ gidigidi! 26 Mo pàṣẹ pé ní gbogbo ibi tí mo ti ń ṣàkóso, kí àwọn èèyàn máa bẹ̀rù Ọlọ́run Dáníẹ́lì gidigidi.+ Torí òun ni Ọlọ́run alààyè, ó sì máa wà títí láé. Ìjọba rẹ̀ ò ní pa run láé, àkóso* rẹ̀ sì máa wà títí ayérayé.+ 27 Ó ń gbani sílẹ̀,+ ó ń gbani là, ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ní ọ̀run àti ní ayé,+ torí ó gba Dáníẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́* àwọn kìnnìún.”
28 Nǹkan wá túbọ̀ dáa fún Dáníẹ́lì yìí nínú ìjọba Dáríúsì+ àti nínú ìjọba Kírúsì ará Páṣíà.+
7 Ní ọdún kìíní Bẹliṣásárì+ ọba Bábílónì, Dáníẹ́lì lá àlá, ó sì rí àwọn ìran nígbà tó dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀.+ Ó wá kọ àlá náà sílẹ̀;+ ó kọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 2 Dáníẹ́lì sọ pé:
“Mò ń wò nínú ìran tí mo rí ní òru, sì wò ó! atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run ń ru alagbalúgbú òkun sókè.+ 3 Ẹranko ńlá mẹ́rin+ sì jáde látinú òkun, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀ síra.
4 “Èyí àkọ́kọ́ dà bíi kìnnìún,+ ó sì ní ìyẹ́ idì.+ Mò ń wò ó títí a fi fa ìyẹ́ rẹ̀ tu, a sì gbé e sókè lórí ayé, a mú kó fi ẹsẹ̀ méjì dúró bí èèyàn, a sì fún un ní ọkàn èèyàn.
5 “Wò ó! ẹranko míì, èkejì, ó dà bíi bíárì.+ A gbé e sókè lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, egungun ìhà mẹ́ta sì wà ní ẹnu rẹ̀ láàárín eyín rẹ̀; a sì sọ fún un pé, ‘Dìde, jẹ ẹran púpọ̀.’+
6 “Lẹ́yìn èyí, mò ń wò, sì wò ó! ẹranko míì tó dà bí àmọ̀tẹ́kùn,+ àmọ́ tó ní ìyẹ́ mẹ́rin bíi ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ẹranko náà ní orí mẹ́rin,+ a sì fún un ní àṣẹ láti ṣàkóso.
7 “Lẹ́yìn èyí, mò ń wò nínú ìran òru, mo sì rí ẹranko kẹrin, ó ń bani lẹ́rù, ó sì ń dáyà jáni, agbára rẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì ní eyín ńlá tó jẹ́ irin. Ó ń jẹ nǹkan run, ó ń fọ́ nǹkan túútúú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ ohun tó ṣẹ́ kù mọ́lẹ̀.+ Ó yàtọ̀ sí gbogbo ẹranko yòókù tó wà ṣáájú rẹ̀, ó sì ní ìwo mẹ́wàá. 8 Bí mo ṣe ń ronú nípa àwọn ìwo náà, wò ó! ìwo míì tó kéré + jáde láàárín wọn, a sì fa mẹ́ta lára àwọn ìwo àkọ́kọ́ tu kúrò níwájú rẹ̀. Wò ó! ojú tó dà bíi ti èèyàn wà lára ìwo yìí, ó sì ní ẹnu tó ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.*+
9 “Mò ń wò títí a fi gbé àwọn ìtẹ́ kalẹ̀, tí Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé+ sì jókòó.+ Aṣọ rẹ̀ funfun bíi yìnyín,+ irun orí rẹ̀ sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ọwọ́ iná ni ìtẹ́ rẹ̀; iná tó ń jó ni àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀.+ 10 Iná ń ṣàn jáde lọ níwájú rẹ̀.+ Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì dúró níwájú rẹ̀.+ Kọ́ọ̀tù+ jókòó, a sì ṣí àwọn ìwé.
11 “Mò ń wò nígbà yẹn torí bí mo ṣe ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga* tí ìwo náà ń sọ;+ mò ń wò ó títí a fi pa ẹranko náà, tí a pa ara rẹ̀ run, a sì jù ú sínú iná kó lè jó o. 12 Àmọ́ ní ti àwọn ẹranko yòókù,+ a gba àkóso lọ́wọ́ wọn, a sì mú kí ẹ̀mí wọn gùn sí i fún ìgbà kan àti àsìkò kan.
13 “Mò ń wò nínú ìran òru, sì wò ó! ẹnì kan bí ọmọ èèyàn+ ń bọ̀ pẹ̀lú ìkùukùu* ojú ọ̀run; a jẹ́ kó wọlé wá sọ́dọ̀ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,+ wọ́n sì mú un wá sún mọ́ iwájú Ẹni yẹn. 14 A sì fún un ní àkóso,+ ọlá+ àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà máa sìn ín.+ Àkóso rẹ̀ jẹ́ àkóso tó máa wà títí láé, tí kò ní kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ ò sì ní pa run.+
15 “Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, ìdààmú bá ẹ̀mí mi nínú mi, torí àwọn ìran tí mo rí dẹ́rù bà mí.+ 16 Mo sún mọ́ ọ̀kan lára àwọn tó dúró síbẹ̀, kí n lè bi í ní ohun tí èyí túmọ̀ sí gan-an. Ó dá mi lóhùn, ó sì sọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan yìí fún mi.
17 “‘Ẹranko ńlá mẹ́rin+ yìí ni ọba mẹ́rin tó máa dìde ní ayé.+ 18 Àmọ́ àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ+ máa gba ìjọba,+ ìjọba náà sì máa jẹ́ tiwọn+ títí láé, àní títí láé àti láéláé.’
19 “Mo fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹranko kẹrin, tó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn yòókù; ó ń bani lẹ́rù lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó ní eyín irin àti èékánná bàbà, ó ń jẹ nǹkan run, ó ń fọ́ nǹkan túútúú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ ohun tó ṣẹ́ kù mọ́lẹ̀;+ 20 àti nípa ìwo mẹ́wàá+ tó wà ní orí rẹ̀ àti ìwo míì tó jáde, tí mẹ́ta sì ṣubú níwájú rẹ̀,+ ìwo tó ní ojú àti ẹnu tó ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga,* tí ìrísí rẹ̀ sì tóbi ju ti àwọn yòókù.
21 “Mò ń wò ó bí ìwo yẹn ṣe bá àwọn ẹni mímọ́ jagun, ó sì ń borí wọn,+ 22 títí Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé+ fi dé, tí a sì dá àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ láre,+ àkókò tí a yàn pé kí àwọn ẹni mímọ́ gba ìjọba sì dé.+
23 “Ohun tó sọ nìyí: ‘Ní ti ẹranko kẹrin, ìjọba kẹrin máa wà ní ayé. Ó máa yàtọ̀ sí gbogbo ìjọba yòókù, ó máa jẹ gbogbo ayé run, ó máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, ó sì máa fọ́ ọ túútúú.+ 24 Ní ti ìwo mẹ́wàá náà, ọba mẹ́wàá máa dìde látinú ìjọba yẹn, òmíràn tún máa dìde lẹ́yìn wọn, ó máa yàtọ̀ sí àwọn ti àkọ́kọ́, ó sì máa rẹ ọba mẹ́ta wálẹ̀.+ 25 Ó máa sọ̀rọ̀ sí Ẹni Gíga Jù Lọ,+ á sì máa fòòró àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ. Ó máa gbèrò láti yí àwọn àkókò àti òfin pa dà, a sì máa fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún àkókò kan, àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò.*+ 26 Àmọ́ Kọ́ọ̀tù jókòó, wọ́n gba àkóso lọ́wọ́ rẹ̀, kí wọ́n lè pa á rẹ́, kí wọ́n sì pa á run pátápátá.+
27 “‘A sì fún àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ ní ìjọba, àkóso àti títóbi àwọn ìjọba lábẹ́ gbogbo ọ̀run.+ Ìjọba tó máa wà títí láé ni ìjọba wọn,+ gbogbo ìjọba á máa sìn wọ́n, wọ́n á sì máa ṣègbọràn sí wọn.’
28 “Òpin ọ̀rọ̀ náà nìyí. Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, èrò ọkàn mi dẹ́rù bà mí gan-an, débi pé ara mi funfun;* àmọ́ mo fi ọ̀rọ̀ náà pa mọ́ sínú ọkàn mi.”
8 Ní ọdún kẹta àkóso Ọba Bẹliṣásárì,+ èmi Dáníẹ́lì rí ìran kan, lẹ́yìn èyí tí mo kọ́kọ́ rí.+ 2 Mo rí ìran náà, bí mo sì ṣe ń wò ó, mo wà ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá,* tó wà ní ìpínlẹ̀* Élámù;+ mo rí ìran náà, mo sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ipadò Úláì. 3 Nígbà tí mo gbé ojú mi sókè, wò ó! àgbò+ kan dúró níwájú ipadò náà, ó sì ní ìwo méjì.+ Ìwo méjèèjì ga, àmọ́ ọ̀kan ga ju ìkejì lọ, èyí tó ga jù sì jáde wá lẹ́yìn náà.+ 4 Mo rí i tí àgbò náà ń kàn ní ìwọ̀ oòrùn, àríwá àti gúúsù, kò sí ẹran inú igbó kankan tó lè dúró níwájú rẹ̀, kò sì sí ẹni tó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.*+ Ohun tó wù ú ló ń ṣe, ó sì gbé ara rẹ̀ ga.
5 Bí mo ṣe ń wò, mo rí òbúkọ+ kan tó ń bọ̀ láti ìwọ̀ oòrùn,* ó ń kọjá lọ ní gbogbo ayé láìfi ẹsẹ̀ kanlẹ̀. Òbúkọ náà sì ní ìwo kan tó hàn kedere láàárín àwọn ojú rẹ̀.+ 6 Ó ń bọ̀ lọ́dọ̀ àgbò tó ní ìwo méjì náà, tí mo rí tó dúró níwájú ipadò; ó ń sáré bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú tó le gan-an.
7 Mo rí i tó ń sún mọ́ àgbò náà, ó sì kórìíra rẹ̀ gan-an. Ó lu àgbò náà bolẹ̀, ó ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì, àgbò náà ò sì lágbára láti dìde sí i. Ó la àgbò náà mọ́lẹ̀, ó sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kò sì sẹ́ni tó gba àgbò náà lọ́wọ́ rẹ̀.*
8 Òbúkọ náà wá gbé ara rẹ̀ ga kọjá ààlà, àmọ́ gbàrà tó di alágbára, ìwo ńlá náà ṣẹ́; ìwo mẹ́rin tó hàn kedere sì jáde dípò ìwo kan ṣoṣo náà, wọ́n dojú kọ atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.+
9 Ìwo míì jáde látinú ọ̀kan lára wọn, ìwo kékeré ni, ó sì di ńlá gan-an, sí apá gúúsù, sí apá ìlà oòrùn* àti sí Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.*+ 10 Ó di ńlá débi pé ó dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ogun ọ̀run lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún, ó sì mú kí àwọn ọmọ ogun kan àti àwọn ìràwọ̀ kan já bọ́ sí ayé, ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. 11 Ó gbéra ga sí Olórí àwọn ọmọ ogun pàápàá, a sì mú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo* kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, a sì wó ibi tó fìdí múlẹ̀ ní ibi mímọ́ rẹ̀ lulẹ̀.+ 12 A fi àwọn ọmọ ogun kan léni lọ́wọ́, pẹ̀lú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo,* torí ẹ̀ṣẹ̀; ó sì ń wó òtítọ́ lulẹ̀ ṣáá, ó gbé ìgbésẹ̀, ó sì ṣàṣeyọrí.
13 Mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ kan ń sọ̀rọ̀, ẹni mímọ́ míì sì sọ fún ẹni tó ń sọ̀rọ̀ pé: “Báwo ni ìran ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo* àti ti ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa ìsọdahoro ṣe máa pẹ́ tó,+ láti sọ ibi mímọ́ náà àti àwọn ọmọ ogun náà di ohun tí wọ́n ń tẹ̀ mọ́lẹ̀?” 14 Ó wá sọ fún mi pé: “Títí di ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (2,300) alẹ́ àti àárọ̀; ó dájú pé ibi mímọ́ náà máa pa dà sí bó ṣe yẹ kó wà.”
15 Bí èmi Dáníẹ́lì ṣe ń rí ìran náà, tí mo sì ń wá bó ṣe máa yé mi, ṣàdédé ni mo rí ẹnì kan tó rí bí èèyàn, tó dúró níwájú mi. 16 Mo wá gbọ́ ohùn èèyàn kan láàárín Úláì,+ ó sì ké jáde pé: “Gébúrẹ́lì,+ jẹ́ kí ẹni yẹn lóye ohun tó rí.”+ 17 Torí náà, ó sún mọ́ ibi tí mo dúró sí, àmọ́ nígbà tó dé, ẹ̀rù bà mí débi pé mo dojú bolẹ̀. Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jẹ́ kó yé ọ pé àkókò òpin ni ìran náà wà fún.”+ 18 Àmọ́ bó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo sùn lọ fọnfọn níbi tí mo dojú bolẹ̀ sí. Ó wá fọwọ́ kàn mí, ó sì mú kí n dìde dúró níbi tí mo dúró sí.+ 19 Ó wá sọ pé: “Mo fẹ́ kí o mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní apá ìparí ìdálẹ́bi náà, torí àkókò òpin tí a yàn ló wà fún.+
20 “Àgbò oníwo méjì tí o rí dúró fún àwọn ọba Mídíà àti Páṣíà.+ 21 Òbúkọ onírun náà dúró fún ọba ilẹ̀ Gíríìsì;+ ìwo ńlá tó wà láàárín àwọn ojú rẹ̀ sì dúró fún ọba àkọ́kọ́.+ 22 Ní ti ìwo tó ṣẹ́, tí mẹ́rin fi jáde dípò rẹ̀,+ ìjọba mẹ́rin máa dìde láti orílẹ̀-èdè rẹ̀, àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú agbára rẹ̀.
23 “Ní apá ìparí ìjọba wọn, bí ìṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ṣe ń parí,* ọba kan tí ojú rẹ̀ le, tó lóye àwọn ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ púpọ̀,* máa dìde. 24 Ó máa lágbára gan-an, àmọ́ kì í ṣe nípa agbára òun fúnra rẹ̀. Ó máa mú ìparun wá lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀,* ó máa ṣàṣeyọrí, ó sì máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́. Ó máa pa àwọn alágbára run àti àwọn tó jẹ́ ẹni mímọ́.+ 25 Nípasẹ̀ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀, ó máa fi ẹ̀tàn ṣàṣeyọrí; ó máa gbéra ga nínú ọkàn rẹ̀; ó sì máa pa ọ̀pọ̀ run ní àkókò ààbò.* Ó tiẹ̀ máa dìde sí Olórí àwọn ọmọ aládé, àmọ́ a máa ṣẹ́ ẹ láìsí ọwọ́ èèyàn.
26 “Òótọ́ ni ohun tí wọ́n sọ nínú ìran náà nípa alẹ́ àti àárọ̀, àmọ́ kí o ṣe ìran náà ní àṣírí, torí ọ̀pọ̀ ọjọ́ sí àkókò yìí* ló ń tọ́ka sí.”+
27 Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, okun tán nínú mi, ara mi ò sì yá fún ọjọ́ mélòó kan.+ Mo wá dìde, mo sì ń bá iṣẹ́ ọba lọ;+ àmọ́ ohun tí mo rí jẹ́ kí ara mi kú tipiri, kò sì sẹ́ni tó yé.+
9 Ní ọdún kìíní Dáríúsì+ ọmọ Ahasuérúsì, àtọmọdọ́mọ àwọn ará Mídíà, ẹni tí wọ́n fi jọba lórí ìjọba àwọn ará Kálídíà,+ 2 ní ọdún kìíní ìjọba rẹ̀, èmi Dáníẹ́lì fi òye mọ̀ látinú ìwé,* iye ọdún tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà pé Jerúsálẹ́mù fi máa wà ní ahoro,+ ìyẹn àádọ́rin (70) ọdún.+ 3 Mo wá yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, mo bẹ̀ ẹ́ bí mo ṣe ń gbàdúrà sí i, pẹ̀lú ààwẹ̀,+ aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú. 4 Mo gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run mi, mo jẹ́wọ́, mo sì sọ pé:
“Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni ńlá, tó yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+ 5 a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe ohun tí kò dáa, a ti hùwà burúkú, a sì ti ṣọ̀tẹ̀;+ a ti kọ àwọn àṣẹ rẹ àti àwọn ìdájọ́ rẹ sílẹ̀. 6 A ò fetí sí àwọn wòlíì tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ,+ tí wọ́n bá àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa, àwọn baba ńlá wa àti gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ. 7 Jèhófà, tìrẹ ni òdodo, àmọ́ àwa ni ìtìjú bá, bó ṣe rí lónìí yìí, àwa èèyàn Júdà, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn tó wà nítòsí àti lọ́nà jíjìn, ní gbogbo ilẹ̀ tí o fọ́n wọn ká sí torí pé wọn ò jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.+
8 “Jèhófà, àwa ni ìtìjú bá, àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa àti àwọn baba ńlá wa, torí pé a ti ṣẹ̀ ọ́. 9 Àánú àti ìdáríjì jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run wa,+ torí a ti ṣọ̀tẹ̀ sí i.+ 10 A ò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa nípa títẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀ tó fún wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 11 Gbogbo Ísírẹ́lì ti tẹ Òfin rẹ lójú, wọ́n sì ti yà kúrò nínú rẹ̀ torí pé wọn ò ṣègbọràn sí ohùn rẹ, tí o fi da ègún àti ìbúra lé wa lórí, èyí tí wọ́n kọ sínú Òfin Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́,+ torí pé a ti ṣẹ̀ Ẹ́. 12 Ó ti ṣe ohun tó sọ lòdì sí àwa+ àti àwọn alákòóso wa tí wọ́n jọba lé wa lórí,* torí ó mú kí àjálù ńlá ṣẹlẹ̀ sí wa; ohunkóhun ò ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ gbogbo ọ̀run bí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.+ 13 Bí a ṣe kọ ọ́ sínú Òfin Mósè, gbogbo àjálù yìí ti dé bá wa,+ síbẹ̀ a kò bẹ Jèhófà Ọlọ́run wa pé* kó ṣojúure sí wa, nípa yíyí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ ká sì fi ìjìnlẹ̀ òye hàn nínú òótọ́* rẹ.
14 “Torí náà, Jèhófà wà lójúfò, ó sì mú àjálù bá wa, torí Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ olódodo nínú gbogbo iṣẹ́ tó ti ṣe; síbẹ̀, a ò ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀.+
15 “Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run wa, Ìwọ tí o fi ọwọ́ agbára mú àwọn èèyàn rẹ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ tí o sì ṣe orúkọ fún ara rẹ títí di òní yìí,+ a ti ṣẹ̀, a sì ti hùwà burúkú. 16 Jèhófà, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo ìṣe òdodo rẹ,+ jọ̀ọ́, dáwọ́ ìbínú àti ìrunú rẹ dúró lórí ìlú rẹ, Jerúsálẹ́mù, òkè mímọ́ rẹ; torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣìṣe àwọn baba ńlá wa, gbogbo àwọn tó yí wa ká ń gan Jerúsálẹ́mù àti àwọn èèyàn rẹ.+ 17 Ní báyìí, Ọlọ́run wa, fetí sílẹ̀ sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ tàn sára ibi mímọ́ rẹ+ tó ti di ahoro,+ torí tìẹ, Jèhófà. 18 Ọlọ́run mi, tẹ́tí sílẹ̀, kí o sì gbọ́! La ojú rẹ, kí o sì rí ìyà tó ń jẹ wá àti bí ìlú tí a fi orúkọ rẹ pè ṣe di ahoro; kì í ṣe torí àwọn ìṣe òdodo wa la ṣe ń bẹ̀ ọ́, torí àánú rẹ tó pọ̀ ni.+ 19 Jèhófà, jọ̀ọ́ tẹ́tí gbọ́. Jèhófà, jọ̀ọ́ dárí jì.+ Jèhófà, jọ̀ọ́ fiyè sí wa, kí o sì gbé ìgbésẹ̀! Má ṣe jẹ́ kó pẹ́, torí tìẹ, Ọlọ́run mi, torí orúkọ rẹ la fi pe ìlú rẹ àti àwọn èèyàn rẹ.”+
20 Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, tí mò ń gbàdúrà, tí mò ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì, tí mo sì ń bẹ̀bẹ̀ fún ojúure Jèhófà Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ Ọlọ́run mi,+ 21 àní, bí mo ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́, ọkùnrin náà Gébúrẹ́lì,+ ẹni tí mo ti rí nínú ìran tẹ́lẹ̀,+ wá sọ́dọ̀ mi nígbà tí okun ti tán nínú mi pátápátá, nígbà tí àkókò ọrẹ alẹ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó. 22 Ó sì là mí lóye, ó sọ pé:
“Ìwọ Dáníẹ́lì, mo wá láti fún ọ ní ìjìnlẹ̀ òye àti ìmọ̀. 23 Nígbà tí o bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀bẹ̀, ọ̀rọ̀ jáde lọ, mo sì wá ròyìn rẹ̀ fún ọ, torí o ṣeyebíye gan-an.*+ Torí náà, ro ọ̀rọ̀ náà, kí ìran náà sì yé ọ.
24 “A ti pinnu àádọ́rin (70) ọ̀sẹ̀* fún àwọn èèyàn rẹ àti ìlú mímọ́ rẹ,+ láti fòpin sí àṣìṣe, láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́,+ láti ṣe ètùtù torí ìṣìnà,+ láti mú òdodo tó máa wà títí láé wá,+ láti gbé èdìdì lé ìran náà àti àsọtẹ́lẹ̀*+ àti láti fòróró yan Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́.* 25 Mọ èyí, kó sì yé ọ pé látìgbà tí a bá ti pàṣẹ pé ká dá Jerúsálẹ́mù pa dà sí bó ṣe wà,+ ká sì tún un kọ́, títí di ìgbà Mèsáyà*+ Aṣáájú,+ ọ̀sẹ̀ méje máa wà àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta (62).+ Wọ́n máa mú kó pa dà sí bó ṣe wà, wọ́n sì máa tún un kọ́, ó máa ní ojúde ìlú, wọ́n sì máa gbẹ́ kòtò ńlá yí i ká, àmọ́ á jẹ́ ní àkókò wàhálà.
26 “Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta (62) náà, wọ́n máa pa Mèsáyà,*+ láìṣẹ́ ohunkóhun kù fún ara rẹ̀.+
“Àwọn èèyàn aṣáájú tó ń bọ̀ máa pa ìlú náà àti ibi mímọ́ náà run.+ Àkúnya omi ló sì máa fòpin sí i. Ogun á sì máa jà títí dé òpin; a ti pinnu pé ó máa di ahoro.+
27 “Ó máa mú kí májẹ̀mú náà wà lẹ́nu iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, fún ọ̀sẹ̀ kan; ní ìdajì ọ̀sẹ̀ náà, ó máa mú kí ẹbọ àti ọrẹ dópin.+
“Ẹni tó ń sọ nǹkan di ahoro máa wà lórí ìyẹ́ àwọn ohun ìríra;+ títí dìgbà ìparun, a máa da ohun tí a pinnu sórí ẹni tó ti di ahoro pẹ̀lú.”
10 Ní ọdún kẹta Kírúsì+ ọba Páṣíà, a ṣí ọ̀rọ̀ kan payá fún Dáníẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹtiṣásárì;+ òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó dá lórí ìjàkadì ńlá kan. Ọ̀rọ̀ náà yé e, a sì jẹ́ kí ohun tó rí yé e.
2 Nígbà yẹn, èmi Dáníẹ́lì ti ń ṣọ̀fọ̀+ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko. 3 Mi ò jẹ oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀, ẹran tàbí wáìnì kò kan ẹnu mi, mi ò sì fi òróró para rárá fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko. 4 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kìíní, nígbà tí mo wà létí odò ńlá náà, ìyẹn Tígírísì,*+ 5 mo wòkè, mo sì rí ọkùnrin kan tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,*+ ó sì de àmùrè wúrà tó wá láti Úfásì mọ́ ìbàdí rẹ̀. 6 Ara rẹ̀ dà bíi kírísóláítì,+ ojú rẹ̀ rí bíi mànàmáná, ẹyinjú rẹ̀ dà bí ògùṣọ̀ oníná, apá rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bíi bàbà tó ń dán,+ ìró ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dà bí ìró èrò púpọ̀. 7 Èmi Dáníẹ́lì nìkan ni mo rí ìran náà; àwọn ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ mi ò rí ìran náà.+ Síbẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sá lọ, wọ́n sì fara pa mọ́.
8 Ó wá ku èmi nìkan, nígbà tí mo sì rí ìran ńlá yìí, agbára kankan ò ṣẹ́ kù nínú mi, ojú mi tó fani mọ́ra tẹ́lẹ̀ yí pa dà, mi ò sì lókun mọ́ rárá.+ 9 Mo wá gbọ́ tó ń sọ̀rọ̀; àmọ́ nígbà tí mo gbọ́ tó ń sọ̀rọ̀, mo sùn lọ fọnfọn ní ìdojúbolẹ̀.+ 10 Ọwọ́ kan sì kàn mí,+ ó jí mi pé kí n dìde lórí ọwọ́ mi àti orúnkún mi. 11 Ó wá sọ fún mi pé:
“Dáníẹ́lì, ìwọ ọkùnrin tó ṣeyebíye gan-an,*+ fiyè sí ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ fún ọ. Ó yá, dìde níbi tí o wà, torí a ti rán mi sí ọ.”
Nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí fún mi, mo dìde, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n.
12 Ó wá sọ fún mi pé: “Má bẹ̀rù,+ ìwọ Dáníẹ́lì. A ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ láti ọjọ́ tí o ti kọ́kọ́ jẹ́ kí ọkàn rẹ lóye, tí o ti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, torí ọ̀rọ̀ rẹ ni mo sì ṣe wá.+ 13 Àmọ́ olórí+ ilẹ̀ ọba Páṣíà dí mi lọ́nà fún ọjọ́ mọ́kànlélógún (21). Ṣùgbọ́n Máíkẹ́lì,*+ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ipò wọn ga jù* wá ràn mí lọ́wọ́; mo sì wà níbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọba Páṣíà. 14 Mo wá láti jẹ́ kí o lóye ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn rẹ ní àkókò òpin,+ torí ìran ohun tó ṣì máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni.”+
15 Nígbà tó bá mi sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, mo dojú bolẹ̀, mi ò sì lè sọ̀rọ̀. 16 Ẹnì kan tó rí bí èèyàn wá fọwọ́ kan ètè mi,+ mo sì la ẹnu mi, mo sọ fún ẹni tó dúró níwájú mi pé: “Olúwa mi, ìran náà ń kó jìnnìjìnnì bá mi, mi ò sì lókun rárá.+ 17 Báwo ni ìránṣẹ́ olúwa mi ṣe wá fẹ́ bá olúwa mi sọ̀rọ̀?+ Mi ò lókun kankan báyìí, èémí kankan ò sì ṣẹ́ kù nínú mi.”+
18 Ẹni tó rí bí èèyàn náà tún fọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi lókun.+ 19 Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Má bẹ̀rù,+ ìwọ ọkùnrin tó ṣeyebíye gan-an.*+ Kí o ní àlàáfíà.+ Jẹ́ alágbára, àní kí o jẹ́ alágbára.” Bó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo lókun, mo sì sọ pé: “Kí olúwa mi sọ̀rọ̀, torí o ti fún mi lókun.”
20 Ó wá sọ pé: “Ṣé o mọ ìdí tí mo fi wá bá ọ? Ní báyìí, màá pa dà lọ bá olórí Páṣíà jà.+ Tí mo bá kúrò, olórí ilẹ̀ Gíríìsì máa wá. 21 Àmọ́, màá sọ àwọn nǹkan tí a kọ sínú ìwé òtítọ́ fún ọ. Kò sí ẹni tó ń tì mí lẹ́yìn gbágbáágbá nínú àwọn nǹkan yìí, àfi Máíkẹ́lì,+ olórí yín.+
11 “Ní tèmi, ní ọdún kìíní Dáríúsì+ ará Mídíà, mo dìde láti fún un lókun, kí n sì fún un lágbára.* 2 Òótọ́ ni ohun tí mo fẹ́ sọ fún ọ báyìí:
“Wò ó! Ọba mẹ́ta míì máa dìde fún Páṣíà, ìkẹrin máa kó ọrọ̀ tó pọ̀ jọ ju ti gbogbo àwọn yòókù lọ. Tí ọrọ̀ rẹ̀ bá sì ti mú kó di alágbára, ó máa gbé ohun gbogbo dìde sí ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì.+
3 “Ọba kan tó lágbára máa dìde, ìṣàkóso rẹ̀ máa gbilẹ̀,+ á sì máa ṣe ohun tó wù ú. 4 Àmọ́ tó bá ti dìde, ìjọba rẹ̀ máa fọ́, ó sì máa pín sí ọ̀nà atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run,+ àmọ́ kì í ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀,* àkóso wọn ò sì ní lágbára bíi tiẹ̀; torí a máa fa ìjọba rẹ̀ tu, ó sì máa di ti àwọn míì yàtọ̀ sí àwọn yìí.
5 “Ọba gúúsù máa di alágbára, ìyẹn ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè rẹ̀; àmọ́ ọ̀kan máa borí rẹ̀, ìṣàkóso rẹ̀ máa gbilẹ̀, ó sì máa lágbára ju ti ẹni yẹn lọ.
6 “Lẹ́yìn ọdún mélòó kan, wọ́n máa lẹ̀dí àpò pọ̀, ọmọbìnrin ọba gúúsù máa wá bá ọba àríwá láti ṣètò nǹkan lọ́gbọọgba.* Àmọ́ kò ní sí agbára ní apá ọmọbìnrin náà mọ́; ọkùnrin náà ò ní dúró, bẹ́ẹ̀ sì ni apá rẹ̀; a sì máa fi ọmọbìnrin náà léni lọ́wọ́, òun àti àwọn tó ń mú un wọlé, ẹni tó bí i àti ẹni tó ń fún un lágbára ní àkókò yẹn. 7 Ọ̀kan nínú àwọn tó hù látinú gbòǹgbò rẹ̀ máa dìde ní ipò ọkùnrin náà, ó máa wá bá àwọn ọmọ ogun, ó sì máa dìde sí ibi ààbò ọba àríwá, ó máa gbéjà kò wọ́n, ó sì máa borí. 8 Ó tún máa wá sí Íjíbítì pẹ̀lú àwọn ọlọ́run wọn, ère onírin* wọn, àwọn ohun èlò fàdákà àti wúrà wọn tó fani mọ́ra* àti àwọn ẹrú. Ó máa ta kété sí ọba àríwá fún ọdún mélòó kan, 9 ẹni tó máa wá gbéjà ko ìjọba ọba gúúsù, àmọ́ ó máa pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀.
10 “Ní ti àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n máa múra ogun, wọ́n sì máa kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọmọ ogun jọ. Ó dájú pé ó máa gbéra, ó sì máa rọ́ lọ bí àkúnya omi. Àmọ́ ó máa pa dà, ó sì máa jagun títí dé ibi ààbò rẹ̀.
11 “Inú máa bí ọba gúúsù, ó sì máa lọ bá a jà, ìyẹn, ọba àríwá; ó máa kó èrò púpọ̀ jọ, àmọ́ a máa fi àwọn èrò náà lé ẹni yẹn lọ́wọ́. 12 Wọ́n máa kó àwọn èrò náà lọ. Ó máa gbé ọkàn rẹ̀ ga, ó sì máa mú kí ẹgbẹẹgbàárùn-ún ṣubú; àmọ́ kò ní lo ipò gíga rẹ̀.
13 “Ọba àríwá máa wá pa dà, ó sì máa kó èrò tó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́ jọ; ní òpin àwọn àkókò, lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ó dájú pé ó máa kó ọ̀pọ̀ ọmọ ogun àti ẹrù tó pọ̀ wá. 14 Ní àkókò yẹn, ọ̀pọ̀ máa dìde sí ọba gúúsù.
“A sì máa gbé àwọn oníwà ipá* lára àwọn èèyàn rẹ lọ, kí wọ́n lè gbìyànjú láti mú kí ìran kan ṣẹ; àmọ́ wọ́n máa kọsẹ̀.
15 “Ọba àríwá máa wá, ó máa mọ òkìtì láti gbógun tì í, ó sì máa gba ìlú olódi. Àwọn apá* gúúsù kò ní dúró, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ ààyò; wọn ò sì ní lágbára láti dúró. 16 Ẹni tó ń bọ̀ láti gbéjà kò ó máa ṣe ohun tó wù ú, kò sì ní sẹ́ni tó máa dúró níwájú rẹ̀. Ó máa dúró ní ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́,*+ agbára láti pani run sì máa wà ní ọwọ́ rẹ̀. 17 Ó máa pinnu láti wá* pẹ̀lú gbogbo agbára ìjọba rẹ̀, ó máa bá a ṣètò nǹkan lọ́gbọọgba;* ó sì máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́. Ní ti ọmọbìnrin àwọn obìnrin, a máa gbà kí ọkùnrin náà pa á run. Ọmọbìnrin náà ò ní dúró, kò sì ní jẹ́ ti ọkùnrin náà mọ́. 18 Ó máa yíjú pa dà sí àwọn ilẹ̀ etíkun, ó sì máa kó ọ̀pọ̀ lẹ́rú. Ọ̀gágun kan máa mú kí ẹ̀gàn rẹ̀ dópin lórí ara rẹ̀, kí ẹ̀gàn rẹ̀ má bàa sí mọ́. Ó máa mú kó yí pa dà sórí ẹni yẹn. 19 Ó máa wá yí ojú rẹ̀ pa dà sí àwọn ibi ààbò ilẹ̀ rẹ̀, ó máa kọsẹ̀, ó sì máa ṣubú, a ò sì ní rí i.
20 “Ẹnì kan tó ń mú kí afipámúni* la ìjọba ọlọ́lá náà kọjá máa rọ́pò rẹ̀, àmọ́ láàárín ọjọ́ mélòó kan, a máa ṣẹ́ ẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe nínú ìbínú tàbí nípa ogun.
21 “Ẹnì tí a fojú àbùkù wò* máa rọ́pò rẹ̀, wọn ò sì ní fún un ní ọlá ìjọba náà; ó máa wọlé wá ní àkókò ààbò,* ó sì máa fi ọ̀rọ̀ dídùn* gba ìjọba náà. 22 A máa gbá àwọn apá* àkúnya omi náà lọ nítorí rẹ̀, a sì máa ṣẹ́ wọn; bí a ṣe máa ṣe sí Aṣáájú+ májẹ̀mú náà.+ 23 Torí bí wọ́n ṣe bá a lẹ̀dí àpò pọ̀, á máa ṣe ẹ̀tàn, ó máa dìde, ó sì máa di alágbára nípasẹ̀ orílẹ̀-èdè kékeré. 24 Ní àkókò ààbò,* ó máa wá sí àwọn ibi tó dáa jù* ní ìpínlẹ̀* náà, ó sì máa ṣe ohun tí àwọn bàbá rẹ̀ àti àwọn bàbá wọn ò ṣe. Ó máa pín ẹrù ogun, àwọn ohun ìní àti ẹrù láàárín wọn; ó sì máa gbèrò ibi sí àwọn ibi olódi, àmọ́ ó máa jẹ́ fún àkókò kan.
25 “Ó máa fi agbára rẹ̀ àti ọkàn rẹ̀ dojú kọ ọba gúúsù pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun, ọba gúúsù sì máa múra sílẹ̀ fún ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun tó lágbára lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Kò sì ní dúró, torí wọ́n máa gbèrò ibi sí i. 26 Àwọn tó ń jẹ oúnjẹ aládùn rẹ̀ máa fa ìṣubú rẹ̀.
“Ní ti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, a máa gbá wọn lọ,* a sì máa pa ọ̀pọ̀ nínú wọn run.
27 “Ní ti ọba méjì yìí, èrò burúkú máa wà lọ́kàn wọn, wọ́n sì máa jókòó sídìí tábìlì kan náà, wọ́n á máa parọ́ fúnra wọn. Àmọ́ kò sóhun tó máa yọrí sí rere, torí kò tíì tó àkókò tí a yàn pé kí òpin dé.+
28 “Ó máa kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀, ọkàn rẹ̀ sì máa ta ko májẹ̀mú mímọ́. Ó máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́, ó sì máa pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀.
29 “Ní àkókò tí a yàn, ó máa pa dà, ó sì máa wá dojú kọ gúúsù. Àmọ́ ti ọ̀tẹ̀ yìí kò ní rí bíi ti tẹ́lẹ̀, 30 torí àwọn ọkọ̀ òkun Kítímù+ máa wá gbéjà kò ó, a sì máa rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀.
“Ó máa pa dà, ó sì máa dá májẹ̀mú mímọ́ náà lẹ́bi,*+ ó máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́; ó máa pa dà, ó sì máa fiyè sí àwọn tó ń fi májẹ̀mú mímọ́ náà sílẹ̀. 31 Àwọn ọmọ ogun* máa dìde, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀; wọ́n máa sọ ibi mímọ́, ibi ààbò, di aláìmọ́,+ wọ́n sì máa mú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo* kúrò.+
“Wọ́n máa gbé ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀.+
32 “Ó máa fi ọ̀rọ̀ dídùn* mú kí àwọn tó ń ṣe ohun tó lòdì sí májẹ̀mú náà di apẹ̀yìndà. Àmọ́ àwọn tó mọ Ọlọ́run wọn máa borí, wọ́n sì máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́. 33 Àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye+ lára àwọn èèyàn náà máa la ọ̀pọ̀ lóye. A sì máa mú kí wọ́n kọsẹ̀ nípa idà àti ọwọ́ iná, wọ́n á kó wọn lẹ́rú, wọ́n á sì kó wọn lẹ́rù, fún ọjọ́ mélòó kan. 34 Àmọ́ tí a bá ti mú wọn kọsẹ̀, a máa ràn wọ́n lọ́wọ́ díẹ̀; ọ̀pọ̀ sì máa fi ọ̀rọ̀ dídùn* dara pọ̀ mọ́ wọn. 35 A máa mú kí àwọn kan lára àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye kọsẹ̀, ká lè yọ́ wọn mọ́ nítorí wọn, ká wẹ̀ wọ́n mọ́, ká sì sọ wọ́n di funfun+ títí di àkókò òpin; torí pé àkókò tí a yàn kò tíì tó.
36 “Ọba náà máa ṣe ohun tó wù ú, ó máa gbé ara rẹ̀ ga, ó sì máa gbé ara rẹ̀ lékè ju gbogbo ọlọ́run lọ; ó máa sọ àwọn ohun tó yani lẹ́nu sí Ọlọ́run àwọn ọlọ́run.+ Ó máa ṣàṣeyọrí títí ìdálẹ́bi náà fi máa dópin; nítorí ohun tí a ti pinnu gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀. 37 Kò ní ka Ọlọ́run àwọn bàbá rẹ̀ sí; kò ní ka ohun tí àwọn obìnrin fẹ́ tàbí ọlọ́run èyíkéyìí míì sí, ṣùgbọ́n ó máa gbé ara rẹ̀ ga lórí ẹni gbogbo. 38 Àmọ́ dípò ìyẹn,* ó máa yin ọlọ́run ibi ààbò lógo; ọlọ́run tí àwọn bàbá rẹ̀ kò mọ̀ ló máa fi wúrà, fàdákà, àwọn òkúta iyebíye àtàwọn ohun tó fani mọ́ra* yìn lógo. 39 Ó máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́ lòdì sí àwọn ibi ààbò tó lágbára jù, pẹ̀lú* ọlọ́run àjèjì. Ó máa fi ògo ńlá fún àwọn tó kà á sí,* ó sì máa mú kí wọ́n ṣàkóso láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀; ó máa pín ilẹ̀ ní iye kan.
40 “Ní àkókò òpin, ọba gúúsù máa kọ lù ú,* ọba àríwá sì máa fi àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn agẹṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ òkun rọ́ lù ú; ó máa wọ ilẹ̀ náà, ó sì máa rọ́ kọjá bí àkúnya omi. 41 Ó tún máa wọ ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́,*+ a sì máa mú ọ̀pọ̀ ilẹ̀ kọsẹ̀. Àmọ́ àwọn tó máa bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nìyí: Édómù, Móábù àti èyí tó ṣe pàtàkì jù lára àwọn ọmọ Ámónì. 42 Á máa na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí àwọn ilẹ̀ náà; ní ti ilẹ̀ Íjíbítì, kò ní yè bọ́. 43 Ó máa jọba lórí àwọn ìṣúra wúrà àti fàdákà tó fara sin àti lórí gbogbo ohun tó fani mọ́ra* ní Íjíbítì. Àwọn ará Líbíà àti àwọn ará Etiópíà á sì máa tẹ̀ lé e.*
44 “Àmọ́ ìròyìn láti ìlà oòrùn* àti àríwá máa yọ ọ́ lẹ́nu, ó sì máa fi ìbínú tó le gan-an jáde lọ láti pani rẹ́ ráúráú, kó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ run. 45 Ó máa pa àwọn àgọ́ ọba rẹ̀* sáàárín òkun ńlá àti òkè mímọ́ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́;*+ ó máa wá pa run, kò sì ní sẹ́ni tó máa ràn án lọ́wọ́.
12 “Ní àkókò yẹn, Máíkẹ́lì*+ máa dìde, ọmọ aládé ńlá+ tó dúró nítorí àwọn èèyàn rẹ.* Àkókò wàhálà máa wáyé, èyí tí irú rẹ̀ kò wáyé rí látìgbà tí orílẹ̀-èdè ti wà títí di àkókò yẹn. Ní àkókò yẹn, àwọn èèyàn rẹ máa yè bọ́,+ gbogbo àwọn tí orúkọ wọn wà nínú ìwé.+ 2 Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ máa jí, àwọn kan sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn míì sí ẹ̀gàn àti sí ìkórìíra ayérayé.
3 “Àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa tàn yinrin bí òfúrufú, àwọn tí wọ́n sì ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo máa tàn bí ìràwọ̀, títí láé àti láéláé.
4 “Ní tìrẹ, Dáníẹ́lì, ṣe àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, kí o sì gbé èdìdì lé ìwé náà títí di àkókò òpin.+ Ọ̀pọ̀ máa lọ káàkiri,* ìmọ̀ tòótọ́ sì máa pọ̀ yanturu.”+
5 Èmi Dáníẹ́lì wá wò, mo sì rí àwọn méjì míì tó dúró síbẹ̀, ọ̀kan ní etí omi níbí àti ìkejì ní etí omi lọ́hùn-ún.+ 6 Ọ̀kan wá sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,*+ tó wà lórí omi tó ń ṣàn pé: “Ìgbà wo ni àwọn ohun àgbàyanu yìí máa dópin?” 7 Nígbà náà, mo gbọ́ tí ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, tó wà lórí omi tó ń ṣàn sọ̀rọ̀, bó ṣe gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀ sókè ọ̀run, tó sì fi Ẹni tó wà láàyè títí láé búra pé:+ “Ó máa jẹ́ fún àkókò tí a yàn, àwọn àkókò tí a yàn àti ààbọ̀ àkókò.* Gbàrà tí fífọ́ agbára àwọn èèyàn mímọ́ túútúú bá ti dópin,+ gbogbo nǹkan yìí máa dópin.”
8 Ní tèmi, mo gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi;+ mo wá sọ pé: “Olúwa mi, kí làwọn nǹkan yìí máa yọrí sí?”
9 Ó sì sọ pé: “Máa lọ, Dáníẹ́lì, torí pé ọ̀rọ̀ náà máa jẹ́ àṣírí, a sì máa gbé èdìdì lé e títí di àkókò òpin.+ 10 Ọ̀pọ̀ máa wẹ ara wọn mọ́, wọ́n máa sọ ara wọn di funfun, a sì máa yọ́ wọn mọ́.+ Àwọn ẹni burúkú máa hùwà burúkú, kò sì ní yé ìkankan nínú àwọn ẹni burúkú; ṣùgbọ́n àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa lóye.+
11 “Látìgbà tí a bá ti mú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo*+ kúrò, tí a sì ti gbé ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀,+ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti àádọ́rùn-ún (1,290) ọjọ́ máa wà.
12 “Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fojú sọ́nà,* tó sì dé ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùndínlógójì (1,335) ọjọ́!
13 “Àmọ́ ní tìrẹ, máa lọ sí òpin. O máa sinmi, àmọ́ wàá dìde fún ìpín rẹ* ní òpin àwọn ọjọ́.”+
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Ìyẹn, Babilóníà.
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Ní Héb., “ọmọ.”
Tàbí kó jẹ́, “bọ́ wọn.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Ni Onídàájọ́ Mi.”
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Ṣojúure.”
Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ta Ló Dà Bí Ọlọ́run?”
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Ṣèrànwọ́.”
Ìyẹn, orúkọ àwọn ará Bábílónì.
Tàbí “inú rere.”
Ní Héb., “ọmọ.”
Ní Héb., “orí mi.”
Ní Héb., “ọmọ.”
Ní Héb., “lọ́ràá.”
Ní Héb., “ọmọ.”
Ní Héb., “ọmọ.”
Ní Héb., “ẹ̀mí.”
Ìyẹn, àwọn kan tó gbówọ́ nínú wíwoṣẹ́ àti wíwo ìràwọ̀.
Ní Héb., “ẹ̀mí.”
Èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ Da 2:4b sí 7:28 ní ìbẹ̀rẹ̀.
Tàbí kó jẹ́, “ààtàn; òkìtì ìgbẹ́.”
Tàbí “lórí ilẹ̀.”
Ní Árámáíkì, “pẹ̀lú ẹran ara.”
Tàbí “láti ayérayé dé ayérayé.”
Tàbí “amọ̀ tí wọ́n yan (ṣù).”
Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.
Tàbí “ọmọ aráyé,” ìyẹn, àwọn mẹ̀kúnnù.
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Nǹkan bíi mítà 27 (ẹsẹ̀ bàtà 88). Wo Àfikún B14.
Nǹkan bíi mítà 2.7 (ẹsẹ̀ bàtà 8.8). Wo Àfikún B14.
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “fẹ̀sùn èké.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “ìṣesí rẹ̀ sí wọn yí pa dà pátápátá.”
Tàbí “lágbára lórí àwọn ọkùnrin yìí.”
Tàbí “wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn.”
Tàbí kó jẹ́, “ààtàn; òkìtì ìgbẹ́.”
Ní Árámáíkì, “mú kí ọwọ́ Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ròkè.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Ìyẹn, àwọn kan tó gbówọ́ nínú wíwoṣẹ́ àti wíwo ìràwọ̀.
Ní Árámáíkì, “gbogbo ẹran ara.”
Tàbí “ẹ fi gbòǹgbò ìdí rẹ̀ sílẹ̀.”
Tàbí “ẹ fi gbòǹgbò ìdí rẹ̀ sílẹ̀.”
Tàbí “fi gbòǹgbò ìdí igi náà sílẹ̀.”
Tàbí “yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “Ìrísí ọba wá yí pa dà.”
Ìyẹn, àwọn kan tó gbówọ́ nínú wíwoṣẹ́ àti wíwo ìràwọ̀.
Tàbí “Ọkùnrin kan tó kúnjú ìwọ̀n.”
Ìyẹn, àwọn kan tó gbówọ́ nínú wíwoṣẹ́ àti wíwo ìràwọ̀.
Ní Árámáíkì, “tú àwọn kókó.”
Ní Árámáíkì, “tú àwọn kókó.”
Tàbí “ìlú.”
Tàbí “fòfin dè é.”
Tàbí “wíńdò.”
Tàbí kó jẹ́, “wọn ò mú akọrin kankan wọlé.”
Ní Árámáíkì, “oorun rẹ̀ sì dá lójú rẹ̀.”
Tàbí “fẹ̀sùn èké.”
Tàbí “ipò ọba aláṣẹ.”
Tàbí “ní àtẹ́lẹsẹ̀.”
Tàbí “tó ń fọ́nnu.”
Tàbí “ìfọ́nnu.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “tó ń fọ́nnu.”
Ìyẹn, àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀.
Tàbí “ìrísí mi yí pa dà.”
Tàbí “Súsà.”
Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “lábẹ́ agbára rẹ̀.”
Tàbí “ibi tí oòrùn ti ń wọ̀.”
Tàbí “lábẹ́ agbára rẹ̀.”
Tàbí “ibi tí oòrùn ti ń yọ.”
Tàbí “Ẹwà.”
Tàbí “ẹbọ ìgbà gbogbo.”
Tàbí “ẹbọ ìgbà gbogbo.”
Tàbí “ẹbọ ìgbà gbogbo.”
Tàbí “ṣe dé ibi tí agbára wọn mọ.”
Tàbí “tó já fáfá nínú ṣíṣe ohun tó ń rúni lójú.”
Tàbí “Ó máa runlérùnnà.”
Tàbí kó jẹ́, “láìkìlọ̀ fún wọn.”
Tàbí “torí ọjọ́ iwájú lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún.”
Ìyẹn, àwọn ìwé mímọ́.
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Ní Héb., “àwọn adájọ́ wa tí wọ́n dá ẹjọ́ wa.”
Tàbí “a ò tu Jèhófà Ọlọ́run wa lójú pé.”
Tàbí “òdodo.”
Tàbí “fani mọ́ra gan-an; èèyàn pàtàkì ni ọ́.”
Ìyẹn, ọ̀sẹ̀ tó dúró fún ọdún.
Ní Héb., “wòlíì.”
Tàbí “Ibi Mímọ́ Jù Lọ.”
Tàbí “Ẹni Àmì Òróró.”
Tàbí “ké Mèsáyà kúrò.”
Ní Héb., “Hídẹ́kẹ́lì.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “fani mọ́ra gan-an; ọkùnrin pàtàkì.”
Ó túmọ̀ sí “Ta Ló Dà Bí Ọlọ́run?”
Tàbí “ọmọ aládé onípò kìíní.”
Tàbí “fani mọ́ra gan-an; ọkùnrin pàtàkì.”
Tàbí “kí n sì dà bí ilé ààbò fún un.”
Tàbí “ìran tó ń bọ̀.”
Tàbí “ṣe àdéhùn.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “ṣeyebíye.”
Tàbí “àwọn ọmọ olè.”
Tàbí “Àwọn ọmọ ogun.”
Tàbí “Ẹwà.”
Ní Héb., “Ó máa fi ojú sí wíwá.”
Tàbí “bá a ṣe àdéhùn.”
“Afipámúni,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹni tó ń fipá gba owó orí. Tàbí “akóniṣiṣẹ́.”
Tàbí “tí a kórìíra.”
Tàbí kó jẹ́, “láìkìlọ̀ fún wọn.”
Tàbí “ohun tó fani mọ́ra.”
Tàbí “ọmọ ogun.”
Tàbí kó jẹ́, “Láìkìlọ̀ fún wọn.”
Ní Héb., “lọ́ràá.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “ìkún omi máa gbé wọn lọ.”
Tàbí “ó sì máa dojú ìbínú rẹ̀ kọ májẹ̀mú mímọ́ náà.”
Ní Héb., “Àwọn apá.”
Tàbí “ẹbọ ìgbà gbogbo.”
Tàbí “àsọdùn; àìṣòótọ́.”
Tàbí “àsọdùn; àìṣòótọ́.”
Tàbí “dípò rẹ̀.”
Tàbí “ṣeyebíye.”
Tàbí “pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́.”
Tàbí kó jẹ́, “fún ẹnikẹ́ni tó bá kà sí.”
Tàbí “fi ìwo kàn án.”
Tàbí “Ẹwà.”
Tàbí “ṣeyebíye.”
Ní Héb., “wà ní ìṣísẹ̀ rẹ̀.”
Tàbí “ibi tí oòrùn ti ń yọ.”
Tàbí “àgọ́ rẹ̀ tó dà bí ààfin.”
Tàbí “Ẹwà.”
Ó túmọ̀ sí “Ta Ló Dà Bí Ọlọ́run?”
Ní Héb., “àwọn ọmọ àwọn èèyàn rẹ.”
Tàbí “yẹ̀ ẹ́ [ìyẹn, ìwé náà] wò fínnífínní.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Ìyẹn, àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀.
Tàbí “ẹbọ ìgbà gbogbo.”
Tàbí “tó ń retí lójú méjèèjì.”
Tàbí “ní ibi tí a pín ọ sí.”