ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Jóṣúà 1:1-24:33
  • Jóṣúà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jóṣúà
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jóṣúà

JÓṢÚÀ

1 Lẹ́yìn ikú Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà, Jèhófà sọ fún Jóṣúà*+ ọmọ Núnì, ìránṣẹ́+ Mósè pé: 2 “Mósè ìránṣẹ́ mi ti kú.+ Gbéra, kí o sọdá Jọ́dánì, ìwọ àti gbogbo èèyàn yìí, kí ẹ sì lọ sí ilẹ̀ tí mo fẹ́ fún wọn, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 3 Màá fún yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ yín tẹ̀, bí mo ṣe ṣèlérí fún Mósè.+ 4 Ilẹ̀ yín máa jẹ́ láti aginjù títí dé Lẹ́bánónì àti odò ńlá, ìyẹn odò Yúfírétì, gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Hétì,+ títí lọ dé Òkun Ńlá* ní ìwọ̀ oòrùn.*+ 5 Kò sẹ́ni tó máa lè dìde sí ọ ní gbogbo ìgbà tí o bá fi wà láàyè.+ Bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mósè ni màá ṣe wà pẹ̀lú rẹ.+ Mi ò ní pa ọ́ tì, mi ò sì ní fi ọ́ sílẹ̀.+ 6 Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ torí ìwọ lo máa mú kí àwọn èèyàn yìí jogún ilẹ̀ tí mo búra fún àwọn baba ńlá wọn pé màá fún wọn.+

7 “Ṣáà rí i pé o jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi, kí o sì rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo Òfin tí Mósè ìránṣẹ́ mi pa láṣẹ fún ọ. Má yà kúrò nínú rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ kí o lè máa hùwà ọgbọ́n níbikíbi tí o bá lọ.+ 8 Ìwé Òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ,+ kí o máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà á* tọ̀sántòru, kí o lè rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀;+ ìgbà yẹn ni ọ̀nà rẹ máa yọrí sí rere, tí wàá sì máa hùwà ọgbọ́n.+ 9 Ṣebí mo ti pàṣẹ fún ọ? Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, má sì jáyà, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí o bá lọ.”+

10 Jóṣúà wá pàṣẹ fún àwọn olórí àwọn èèyàn náà pé: 11 “Ẹ lọ káàkiri ibùdó, kí ẹ sì pa àṣẹ yìí fún àwọn èèyàn náà pé, ‘Ẹ ṣètò oúnjẹ sílẹ̀, torí ní ọjọ́ mẹ́ta òní, ẹ máa sọdá Jọ́dánì láti lọ gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín pé kó di tiyín.’”+

12 Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè pé: 13 “Ẹ rántí ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ fún yín pé:+ ‘Jèhófà Ọlọ́run yín máa fún yín ní ìsinmi, ó sì ti fún yín ní ilẹ̀ yìí. 14 Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àtàwọn ẹran ọ̀sìn yín á máa gbé ní ilẹ̀ tí Mósè fún yín ní apá ibí yìí* ní Jọ́dánì,+ àmọ́ kí gbogbo ẹ̀yin jagunjagun tó lákíkanjú+ sọdá ṣáájú àwọn arákùnrin yín, kí ẹ tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun.+ Kí ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ 15 títí Jèhófà fi máa fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi, bó ṣe ṣe fún yín, tí àwọn náà á sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún wọn. Kí ẹ wá pa dà sí ilẹ̀ tí wọ́n fún yín pé kí ẹ máa gbé, kí ẹ sì gbà á, ilẹ̀ tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fún yín ní ìlà oòrùn Jọ́dánì.’”+

16 Wọ́n dá Jóṣúà lóhùn pé: “A máa ṣe gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún wa, a sì máa lọ sí ibikíbi tí o bá rán wa.+ 17 Bí a ṣe fetí sí gbogbo ohun tí Mósè sọ gẹ́lẹ́ la máa fetí sí ọ. Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣáà ti wà pẹ̀lú rẹ bó ṣe wà pẹ̀lú Mósè.+ 18 Ṣe la máa pa ẹnikẹ́ni tó bá tàpá sí àṣẹ rẹ, tí kò sì tẹ̀ lé gbogbo ohun tí o bá pa láṣẹ fún un.+ Ìwọ ṣáà ti jẹ́ onígboyà àti alágbára.”+

2 Jóṣúà ọmọ Núnì wá rán ọkùnrin méjì jáde ní bòókẹ́lẹ́ láti Ṣítímù,+ pé kí wọ́n lọ ṣe amí. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ yẹ ilẹ̀ náà wò, pàápàá ilẹ̀ Jẹ́ríkò.” Torí náà, wọ́n lọ, wọ́n dé ilé aṣẹ́wó kan tó ń jẹ́ Ráhábù,+ wọ́n sì dúró sí ibẹ̀. 2 Àwọn kan sọ fún ọba Jẹ́ríkò pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wọlé wá síbí ní alẹ́ yìí láti ṣe amí ilẹ̀ yìí.” 3 Ni ọba Jẹ́ríkò bá ránṣẹ́ sí Ráhábù pé: “Mú àwọn ọkùnrin tó wá síbí jáde, àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, torí ṣe ni wọ́n wá ṣe amí gbogbo ilẹ̀ yìí.”

4 Àmọ́ obìnrin náà mú àwọn ọkùnrin méjèèjì, ó sì fi wọ́n pa mọ́. Ó wá sọ pé: “Òótọ́ ni àwọn ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ mi, àmọ́ mi ò mọ ibi tí wọ́n ti wá. 5 Nígbà tí ilẹ̀ sì ṣú, tó kù díẹ̀ kí wọ́n ti ẹnubodè ìlú ni àwọn ọkùnrin náà jáde. Mi ò mọ ibi tí àwọn ọkùnrin náà lọ, àmọ́ tí ẹ bá tètè sá tẹ̀ lé wọn, ẹ máa bá wọn.” 6 (Àmọ́ obìnrin náà ti mú àwọn amí náà lọ sórí òrùlé, ó sì fi wọ́n pa mọ́ sáàárín pòròpórò ọ̀gbọ̀ tí wọ́n tò sórí òrùlé náà.) 7 Àwọn ọkùnrin náà bá sáré wá àwọn amí náà lọ, wọ́n gba ọ̀nà Jọ́dánì níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò náà,+ wọ́n sì ti ẹnubodè ìlú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí àwọn tó ń wá àwọn amí náà jáde.

8 Kí àwọn ọkùnrin náà tó dùbúlẹ̀ láti sùn, ó lọ bá wọn lórí òrùlé. 9 Ó sì sọ fún wọn pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà máa fún yín ní ilẹ̀ yìí+ àti pé ẹ̀rù yín ti ń bà wá.+ Ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí sì ti domi nítorí yín,+ 10 torí a ti gbọ́ bí Jèhófà ṣe mú kí omi Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì+ àti ohun tí ẹ ṣe sí àwọn ọba Ámórì méjèèjì, ìyẹn Síhónì+ àti Ógù+ tí ẹ pa run ní òdìkejì* Jọ́dánì. 11 Nígbà tí a gbọ́ nípa rẹ̀, ọkàn wa domi,* kò sì sẹ́ni tó ní ìgboyà* mọ́ nítorí yín, torí Jèhófà Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.+ 12 Ní báyìí, ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi Jèhófà búra fún mi pé ẹ̀yin náà máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí agbo ilé bàbá mi, torí mo ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí yín; kí ẹ fún mi ní àmì kan tó ṣeé gbára lé.* 13 Kí ẹ dá ẹ̀mí bàbá mi àti ìyá mi sí, àwọn arákùnrin mi àtàwọn arábìnrin mi àti gbogbo èèyàn wọn, kí ẹ sì gbà wá* lọ́wọ́ ikú.”+

14 Àwọn ọkùnrin náà sọ fún un pé: “A máa fi ẹ̀mí wa dí tiyín!* Tí o kò bá sọ ohun tí a wá ṣe, a máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn, a sì máa jẹ́ olóòótọ́ sí ọ nígbà tí Jèhófà bá fún wa ní ilẹ̀ náà.” 15 Lẹ́yìn náà, ó fi okùn sọ̀ wọ́n kalẹ̀ láti ojú fèrèsé,* torí pé ẹ̀gbẹ́ kan lára ògiri ìlú náà ni ilé rẹ̀ wà. Kódà, orí ògiri náà ló ń gbé.+ 16 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sí agbègbè olókè, kí ẹ sì sá pa mọ́ síbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kí àwọn tó ń wá yín má bàa rí yín. Tí àwọn tó ń wá yín bá pa dà dé ni kí ẹ tó máa lọ.”

17 Àwọn ọkùnrin náà sọ fún un pé: “A ò ní jẹ̀bi ìbúra tí o mú ká ṣe yìí+ 18 àfi tí a bá dé ilẹ̀ yìí, tí o sì ti so okùn aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí mọ́ ojú fèrèsé tí o gbà sọ̀ wá kalẹ̀. Kí o mú bàbá rẹ, ìyá rẹ, àwọn arákùnrin rẹ àti gbogbo agbo ilé bàbá rẹ wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ilé.+ 19 Tí ẹnikẹ́ni bá wá kúrò nínú ilé rẹ, tó sì jáde sí ìta, òun fúnra rẹ̀ ló máa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀bi náà ò ní sí lọ́rùn wa. Àmọ́ tí aburú bá ṣe* ẹnikẹ́ni tó wà nínú ilé lọ́dọ̀ rẹ, ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ máa wà lọ́rùn wa. 20 Ṣùgbọ́n tí o bá sọ ohun tí a wá ṣe,+ a ò ní jẹ̀bi ìbúra tí o mú ká ṣe yìí.” 21 Ó fèsì pé: “Kó rí bí ẹ ṣe sọ gẹ́lẹ́.”

Ó wá ní kí wọ́n máa lọ, wọ́n sì lọ. Lẹ́yìn náà, ó so okùn aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà mọ́ ojú fèrèsé náà. 22 Ni wọ́n bá kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ sí agbègbè olókè, wọ́n sì dúró síbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, títí àwọn tó wá wọn lọ fi pa dà dé. Àwọn yìí ti wá wọn ní gbogbo ojú ọ̀nà, àmọ́ wọn ò rí wọn. 23 Àwọn ọkùnrin méjèèjì wá sọ̀ kalẹ̀ láti agbègbè olókè, wọ́n sì sọdá odò lọ bá Jóṣúà ọmọ Núnì. Wọ́n ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn fún un. 24 Wọ́n sọ fún Jóṣúà pé: “Jèhófà ti fi gbogbo ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́.+ Kódà, ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà ti domi nítorí wa.”+

3 Jóṣúà wá dìde ní àárọ̀ kùtù, òun àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì* kúrò ní Ṣítímù,+ wọ́n sì lọ sí Jọ́dánì. Wọ́n sun ibẹ̀ mọ́jú kí wọ́n tó sọdá.

2 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, àwọn olórí+ lọ káàkiri ibùdó, 3 wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà pé: “Gbàrà tí ẹ bá rí i tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà+ gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ gbéra láti àyè yín, kí ẹ sì tẹ̀ lé e. 4 Àmọ́ kí ẹ fi àyè tí ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́* sílẹ̀ láàárín ẹ̀yin àti àpótí náà; ẹ má ṣe sún mọ́ ọn rárá, kí ẹ lè mọ ọ̀nà tí ẹ máa gbà, torí pé ẹ ò gba ọ̀nà yìí rí.”

5 Jóṣúà wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ sọ ara yín di mímọ́,+ torí Jèhófà máa ṣe àwọn ohun àgbàyanu láàárín yín lọ́la.”+

6 Jóṣúà sì sọ fún àwọn àlùfáà pé: “Ẹ gbé àpótí+ májẹ̀mú náà, kí ẹ máa nìṣó níwájú àwọn èèyàn náà.” Torí náà, wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú, wọ́n sì ń lọ níwájú àwọn èèyàn náà.

7 Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: “Òní yìí ni mo máa bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì,+ kí wọ́n lè mọ̀ pé màá wà pẹ̀lú rẹ+ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mósè.+ 8 Kí o pa àṣẹ yìí fún àwọn àlùfáà tó gbé àpótí májẹ̀mú náà pé: ‘Tí ẹ bá dé etí odò Jọ́dánì, kí ẹ dúró sínú Jọ́dánì.’”+

9 Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ wá gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín.” 10 Jóṣúà sì sọ pé: “Báyìí lẹ ṣe máa mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè kan wà láàárín yín,+ ó sì dájú pé ó máa lé àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Hífì, àwọn Pérísì, àwọn Gẹ́gáṣì, àwọn Ámórì àti àwọn ará Jébúsì kúrò níwájú yín.+ 11 Ẹ wò ó! Àpótí májẹ̀mú Olúwa gbogbo ayé ń lọ níwájú yín sínú Jọ́dánì. 12 Ẹ mú ọkùnrin méjìlá (12) látinú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan,+ 13 gbàrà tí àtẹ́lẹsẹ̀ àwọn àlùfáà tó gbé Àpótí Jèhófà, Olúwa gbogbo ayé bá kan* omi Jọ́dánì, omi Jọ́dánì tó ń ṣàn wá látòkè máa dáwọ́ dúró, ó sì máa dúró bí ìsédò.”*+

14 Nígbà tí àwọn èèyàn náà kúrò nínú àgọ́ wọn, kété kí wọ́n tó sọdá Jọ́dánì, àwọn àlùfáà tó gbé àpótí+ májẹ̀mú ń lọ níwájú àwọn èèyàn náà. 15 Gbàrà tí àwọn tó gbé Àpótí náà dé Jọ́dánì, tí àwọn àlùfáà tó gbé Àpótí náà sì ki ẹsẹ̀ wọn bọ etí omi náà (ó ṣẹlẹ̀ pé odò Jọ́dánì máa ń kún bo bèbè rẹ̀+ ní gbogbo ọjọ́ ìkórè), 16 omi tó ń ṣàn wá látòkè dáwọ́ dúró. Ó dúró bí ìsédò* síbi tó jìnnà gan-an ní Ádámù, ìlú tó wà nítòsí Sárétánì, èyí tó sì lọ sí Òkun Árábà, Òkun Iyọ̀,* ṣàn lọ títí tó fi gbẹ. Omi odò náà dáwọ́ dúró, àwọn èèyàn náà sì sọdá síbi tó dojú kọ Jẹ́ríkò. 17 Àwọn àlùfáà tó gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà dúró sójú kan lórí ilẹ̀+ ní àárín Jọ́dánì, nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì ń gba orí ilẹ̀ kọjá,+ wọ́n dúró títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi sọdá Jọ́dánì tán.

4 Gbàrà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà sọdá Jọ́dánì tán, Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: 2 “Mú ọkùnrin méjìlá (12) láàárín àwọn èèyàn náà, ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan,+ 3 kí o sì pàṣẹ fún wọn pé: ‘Ẹ gbé òkúta méjìlá (12) ní àárín Jọ́dánì, níbi tí ẹsẹ̀ àwọn àlùfáà tó dúró sójú kan wà,+ kí ẹ gbé àwọn òkúta náà dání, kí ẹ sì tò wọ́n síbi tí ẹ máa sùn mọ́jú.’”+

4 Jóṣúà wá pe ọkùnrin méjìlá (12) tó yàn látinú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, 5 Jóṣúà sì sọ fún wọn pé: “Ẹ kọjá síwájú Àpótí Jèhófà Ọlọ́run yín, sí àárín Jọ́dánì, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín sì gbé òkúta kan sí èjìká rẹ̀, kó jẹ́ iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, 6 kí èyí jẹ́ àmì fún yín. Tí àwọn ọmọ* yín bá bi yín lọ́jọ́ iwájú pé, ‘Kí ni ẹ̀ ń fi àwọn òkúta yìí ṣe?’+ 7 kí ẹ sọ fún wọn pé: ‘Torí omi odò Jọ́dánì tó dáwọ́ dúró níwájú àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà ni. Nígbà tí wọ́n gbé àpótí náà sọdá odò Jọ́dánì, omi odò Jọ́dánì dáwọ́ dúró. Àwọn òkúta yìí máa jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí lọ.’”+

8 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí Jóṣúà sọ gẹ́lẹ́. Wọ́n gbé òkúta méjìlá (12) ní àárín Jọ́dánì, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà, iye òkúta náà jẹ́ iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n kó o lọ síbi tí wọ́n fẹ́ sùn mọ́jú, wọ́n sì tò ó síbẹ̀.

9 Jóṣúà tún to òkúta méjìlá (12) sí àárín Jọ́dánì níbi tí àwọn àlùfáà tí wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú náà dúró sí,+ àwọn òkúta náà sì wà níbẹ̀ títí dòní.

10 Àwọn àlùfáà tó gbé Àpótí náà dúró sí àárín Jọ́dánì títí àwọn èèyàn náà fi parí gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí Jóṣúà sọ fún wọn, bíi gbogbo ohun tí Mósè pa láṣẹ fún Jóṣúà. Ní gbogbo ìgbà yẹn, àwọn èèyàn náà ń yára sọdá. 11 Gbàrà tí gbogbo àwọn èèyàn náà sọdá tán, Àpótí Jèhófà àti àwọn àlùfáà sọdá níṣojú àwọn èèyàn náà.+ 12 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè sọdá ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù, wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun,+ bí Mósè ṣe pa á láṣẹ fún wọn.+ 13 Nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ọmọ ogun tó dira ogun ló sọdá níwájú Jèhófà sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Jẹ́ríkò.

14 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà gbé Jóṣúà ga níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì,+ wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un gan-an* ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, bí wọ́n ṣe bọ̀wọ̀ fún Mósè gidigidi.+

15 Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: 16 “Pàṣẹ fún àwọn àlùfáà tó gbé àpótí+ Ẹ̀rí pé kí wọ́n jáde nínú odò Jọ́dánì.” 17 Ni Jóṣúà bá pàṣẹ fún àwọn àlùfáà náà pé: “Ẹ jáde nínú odò Jọ́dánì.” 18 Nígbà tí àwọn àlùfáà tó gbé àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà jáde ní àárín Jọ́dánì, tí àtẹ́lẹsẹ̀ àwọn àlùfáà náà sì kan orí ilẹ̀, omi odò Jọ́dánì tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàn, ó sì kún bo bèbè rẹ̀+ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.

19 Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìíní, àwọn èèyàn náà kúrò ní Jọ́dánì, wọ́n sì pàgọ́ sí Gílígálì+ ní ààlà Jẹ́ríkò lápá ìlà oòrùn.

20 Ní ti òkúta méjìlá (12) tí wọ́n kó jáde látinú Jọ́dánì, Jóṣúà tò ó sí Gílígálì.+ 21 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Lọ́jọ́ iwájú, tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ àwọn bàbá wọn pé, ‘Kí ni àwọn òkúta yìí wà fún?’+ 22 kí ẹ ṣàlàyé fún àwọn ọmọ yín pé: ‘Orí ilẹ̀ gbígbẹ ni Ísírẹ́lì gbà sọdá Jọ́dánì+ 23 nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run yín mú kí omi Jọ́dánì gbẹ níwájú wọn títí wọ́n fi sọdá, bí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe ṣe sí Òkun Pupa nígbà tó mú kó gbẹ níwájú wa títí a fi sọdá.+ 24 Ó ṣe èyí, kí gbogbo aráyé lè mọ bí ọwọ́ Jèhófà ṣe lágbára tó,+ kí ẹ sì lè máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.’”

5 Gbàrà tí gbogbo ọba àwọn Ámórì,+ tí wọ́n wà lápá ìwọ̀ oòrùn* Jọ́dánì àti gbogbo ọba àwọn ọmọ Kénáánì,+ tí wọ́n wà létí òkun gbọ́ pé Jèhófà ti mú kí omi Jọ́dánì gbẹ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí wọ́n fi sọdá, ọkàn wọn domi,*+ kò sì sí ẹni tó ní ìgboyà mọ́* torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+

2 Ìgbà yẹn ni Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Fi akọ òkúta ṣe àwọn ọ̀bẹ fún ara rẹ, kí o sì tún dádọ̀dọ́*+ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì lẹ́ẹ̀kejì.” 3 Jóṣúà wá fi akọ òkúta ṣe àwọn ọ̀bẹ, ó sì dádọ̀dọ́ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ní Gibeati-háárálótì.*+ 4 Ìdí tí Jóṣúà fi dádọ̀dọ́ wọn ni pé: Gbogbo ọkùnrin tó wà nínú àwọn èèyàn náà, tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, gbogbo ọkùnrin ogun,* ti kú sínú aginjù lẹ́nu ìrìn àjò wọn lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì.+ 5 Gbogbo àwọn tó kúrò ní Íjíbítì ló dádọ̀dọ́, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí wọ́n bí ní aginjù lẹ́nu ìrìn àjò wọn lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì kò tíì dádọ̀dọ́. 6 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi ogójì (40) ọdún+ rìn ní aginjù, títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi kú, ìyẹn àwọn ọkùnrin ogun tó kúrò ní Íjíbítì, tí wọn ò fetí sí ohùn Jèhófà.+ Jèhófà búra fún wọn pé òun kò ní jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀+ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wọn pé òun máa fún wa,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ 7 Ó fi àwọn ọmọ wọn rọ́pò wọn.+ Àwọn yìí ni Jóṣúà dádọ̀dọ́ wọn; aláìdádọ̀dọ́ ni wọ́n torí pé wọn ò tíì dádọ̀dọ́ lẹ́nu ìrìn àjò wọn.

8 Nígbà tí wọ́n dádọ̀dọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè náà tán, wọ́n dúró síbi tí wọ́n pàgọ́ sí títí ara wọn fi jinná.

9 Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: “Mo yí ẹ̀gàn Íjíbítì kúrò lórí yín lónìí.” Wọ́n wá ń pe ibẹ̀ ní Gílígálì*+ títí di òní yìí.

10 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì dúró sí Gílígálì tí wọ́n pàgọ́ sí, wọ́n ṣe Ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù,+ ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Jẹ́ríkò. 11 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ èso ilẹ̀ náà ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé Ìrékọjá, wọ́n jẹ búrẹ́dì aláìwú+ àti àyangbẹ ọkà lọ́jọ́ yẹn kan náà. 12 Mánà ò rọ̀ fún wọn ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ́ tí wọ́n jẹ lára èso ilẹ̀ náà; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò rí mánà kó mọ́,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ èso ilẹ̀ Kénáánì ní ọdún yẹn.+

13 Nígbà tí Jóṣúà wà nítòsí Jẹ́ríkò, ó gbójú sókè, ó sì rí ọkùnrin kan+ tó dúró níwájú rẹ̀, tó fa idà yọ.+ Jóṣúà lọ bá a, ó sì bi í pé: “Ṣé tiwa lò ń ṣe ni, àbí tàwọn ọ̀tá wa?” 14 Ó fèsì pé: “Rárá o, mo wá gẹ́gẹ́ bí olórí* àwọn ọmọ ogun Jèhófà.”+ Ni Jóṣúà bá dojú bolẹ̀, ó sì wólẹ̀, ó sọ fún un pé: “Kí ni olúwa mi fẹ́ sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?” 15 Olórí àwọn ọmọ ogun Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: “Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, torí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí.” Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀ lójú ẹsẹ̀.+

6 Wọ́n ti ìlú Jẹ́ríkò pinpin torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; ẹnì kankan ò jáde, ẹnì kankan ò sì wọlé.+

2 Nígbà náà, Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Wò ó, mo ti fi Jẹ́ríkò àti ọba rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn jagunjagun rẹ̀ tó lákíkanjú.+ 3 Kí gbogbo ẹ̀yin ọkùnrin ogun yan yí ìlú náà ká, kí ẹ lọ yí ká ìlú náà lẹ́ẹ̀kan. Kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. 4 Jẹ́ kí àlùfáà méje mú ìwo àgbò méje dání níwájú Àpótí náà. Àmọ́ ní ọjọ́ keje, kí ẹ yan yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀méje, kí àwọn àlùfáà sì fun àwọn ìwo náà.+ 5 Tí ìwo àgbò náà bá ti dún, gbàrà tí ẹ bá ti gbọ́ ìró ìwo náà,* kí gbogbo èèyàn kígbe tantan láti jagun. Ògiri ìlú náà á wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ,+ kí àwọn èèyàn náà sì gòkè lọ, kí kálukú máa lọ tààràtà.”

6 Jóṣúà ọmọ Núnì wá pe àwọn àlùfáà jọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ gbé àpótí májẹ̀mú, kí àlùfáà méje sì mú ìwo àgbò méje dání níwájú Àpótí Jèhófà.”+ 7 Ó sì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ máa lọ, kí ẹ yan yí ìlú náà ká, kí àwùjọ àwọn ọmọ ogun+ sì máa lọ níwájú Àpótí Jèhófà.” 8 Bí Jóṣúà ṣe sọ fún àwọn èèyàn náà gẹ́lẹ́, àwọn àlùfáà méje tó mú ìwo àgbò méje dání níwájú Jèhófà lọ síwájú, wọ́n sì fun àwọn ìwo náà, àpótí májẹ̀mú Jèhófà sì ń tẹ̀ lé wọn. 9 Àwùjọ àwọn ọmọ ogun náà ń lọ níwájú àwọn àlùfáà tó ń fun ìwo, àwọn ọmọ ogun tó sì wà lẹ́yìn ń tẹ̀ lé Àpótí náà bí wọ́n ṣe ń fun ìwo náà léraléra.

10 Jóṣúà ti pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ kígbe, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbọ́ ohùn yín. Ọ̀rọ̀ kankan ò gbọ́dọ̀ ti ẹnu yín jáde títí di ọjọ́ tí mo bá sọ fún yín pé, ‘Ẹ kígbe!’ Ìgbà yẹn ni kí ẹ kígbe.” 11 Ó mú kí wọ́n gbé Àpótí Jèhófà yí ìlú náà ká, wọ́n gbé e yí i ká lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí ibùdó, wọ́n sì sun ibẹ̀ mọ́jú.

12 Jóṣúà dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, àwọn àlùfáà sì gbé Àpótí+ Jèhófà, 13 àwọn àlùfáà méje tó mú ìwo àgbò méje dání sì ń lọ níwájú Àpótí Jèhófà, wọ́n ń fun ìwo náà léraléra. Àwùjọ àwọn ọmọ ogun ń lọ níwájú wọn, àwọn ọmọ ogun tó sì wà lẹ́yìn ń tẹ̀ lé Àpótí Jèhófà bí wọ́n ṣe ń fun ìwo léraléra. 14 Wọ́n yan yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan ní ọjọ́ kejì, lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí ibùdó. Ohun tí wọ́n ṣe fún ọjọ́ mẹ́fà nìyẹn.+

15 Ní ọjọ́ keje, wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù, gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n sì yan yí ìlú náà ká lọ́nà kan náà lẹ́ẹ̀méje. Ọjọ́ yẹn nìkan ni wọ́n yan yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀méje.+ 16 Ní ìgbà keje, àwọn àlùfáà fun ìwo, Jóṣúà sì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ kígbe,+ torí Jèhófà ti fún yín ní ìlú náà! 17 Kí ẹ pa ìlú náà run àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀;+ Jèhófà ló ni gbogbo rẹ̀. Ráhábù+ aṣẹ́wó nìkan ni kí ẹ dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, òun àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ilé, torí ó fi àwọn tí a rán níṣẹ́ pa mọ́.+ 18 Àmọ́ ẹ yẹra fún ohun tí a máa pa run,+ kí ọkàn yín má bàa fà sí i, kí ẹ sì mú un,+ tí ẹ ó fi mú àjálù* bá ibùdó Ísírẹ́lì, tí ẹ ó sì sọ ọ́ di ohun tí a máa pa run.+ 19 Àmọ́ gbogbo fàdákà, wúrà, àwọn ohun tí wọ́n fi bàbà àti irin ṣe jẹ́ ohun mímọ́ fún Jèhófà.+ Ibi ìṣúra Jèhófà ni kí ẹ kó o lọ.”+

20 Ni àwọn èèyàn náà bá kígbe nígbà tí wọ́n fun ìwo.+ Gbàrà tí àwọn èèyàn náà gbọ́ ìró ìwo, tí wọ́n sì kígbe tantan láti jagun, ògiri ìlú náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ.+ Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn náà wọnú ìlú náà lọ, kálukú ń lọ tààràtà, wọ́n sì gba ìlú náà. 21 Wọ́n fi idà pa gbogbo ohun tó wà nínú ìlú náà run, wọ́n pa ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé àti àgbà, akọ màlúù, àgùntàn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+

22 Jóṣúà sọ fún àwọn ọkùnrin méjì tó lọ ṣe amí ilẹ̀ náà pé: “Ẹ lọ sínú ilé aṣẹ́wó náà, kí ẹ sì mú obìnrin náà àti gbogbo èèyàn rẹ̀ jáde, bí ẹ ṣe búra fún un gẹ́lẹ́.”+ 23 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ṣe amí náà wọlé lọ, wọ́n sì mú Ráhábù, bàbá rẹ̀, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo èèyàn rẹ̀ jáde; àní wọ́n kó gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde,+ wọ́n sì kó wọn wá sí ibì kan lẹ́yìn ibùdó Ísírẹ́lì, ohunkóhun ò ṣe wọ́n.

24 Wọ́n wá dáná sun ìlú náà àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀. Àmọ́ wọ́n kó fàdákà, wúrà àti àwọn ohun tí wọ́n fi bàbà àti irin ṣe lọ síbi ìṣúra nínú ilé Jèhófà.+ 25 Ráhábù àti agbo ilé bàbá rẹ̀ àti gbogbo èèyàn rẹ̀ nìkan ni Jóṣúà dá ẹ̀mí wọn sí;+ ó sì ń gbé ní Ísírẹ́lì títí dòní,+ torí ó fi àwọn tí Jóṣúà rán pé kí wọ́n lọ ṣe amí Jẹ́ríkò pa mọ́.+

26 Ìgbà yẹn ni Jóṣúà búra* pé: “Níwájú Jèhófà, ègún ni fún ẹni tó bá gbìyànjú láti tún ìlú Jẹ́ríkò yìí kọ́. Tó bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀, ẹ̀mí àkọ́bí rẹ̀ ló máa fi dí i, tó bá sì gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nàró, ẹ̀mí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ló máa fi dí i.”+

27 Jèhófà wà pẹ̀lú Jóṣúà,+ òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ayé.+

7 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí kò tọ́ nípa ohun tí wọ́n máa pa run, torí Ákánì+ ọmọ Kámì, ọmọ Sábídì, ọmọ Síírà látinú ẹ̀yà Júdà kó lára àwọn ohun tí wọ́n máa pa run.+ Ìyẹn mú kí Jèhófà bínú gidigidi sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+

2 Jóṣúà wá rán àwọn ọkùnrin jáde láti Jẹ́rìkò lọ sí Áì,+ tó wà nítòsí Bẹti-áfénì, ní ìlà oòrùn Bẹ́tẹ́lì,+ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ gòkè lọ ṣe amí ilẹ̀ náà.” Àwọn ọkùnrin náà sì lọ ṣe amí ìlú Áì. 3 Nígbà tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jóṣúà, wọ́n sọ fún un pé: “Kò pọn dandan kí gbogbo èèyàn lọ. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin ti tó láti ṣẹ́gun ìlú Áì. Má ṣe jẹ́ kí gbogbo èèyàn lọ, kí o má bàa tán wọn lókun torí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀.”

4 Torí náà, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin lọ síbẹ̀, àmọ́ ṣe ni wọ́n sá fún àwọn ọkùnrin Áì.+ 5 Àwọn ọkùnrin Áì pa ọkùnrin mẹ́rìndínlógójì (36), wọ́n sì lé wọn láti ẹ̀yìn ẹnubodè ìlú títí dé Ṣébárímù,* wọ́n ń pa wọ́n ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè. Jìnnìjìnnì bá àwọn èèyàn náà, ọkàn* wọn sì domi.

6 Ni Jóṣúà bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wólẹ̀ níwájú Àpótí Jèhófà títí di ìrọ̀lẹ́, òun àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń da iyẹ̀pẹ̀ sí orí ara wọn. 7 Jóṣúà sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, kí ló dé tí o mú àwọn èèyàn yìí wá láti ìsọdá Jọ́dánì lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún torí kí o kàn lè fi wá lé àwọn Ámórì lọ́wọ́, kí wọ́n sì pa wá dà nù? À bá ti jẹ́ kí òdìkejì* Jọ́dánì tẹ́ wa lọ́rùn, ká sì dúró síbẹ̀! 8 Jọ̀ọ́, Jèhófà, kí ni kí n sọ báyìí tí Ísírẹ́lì ti sá fún* àwọn ọ̀tá rẹ̀? 9 Tí àwọn ọmọ Kénáánì àti gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà bá gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n á yí wa ká, wọ́n á sì pa orúkọ wa rẹ́ kúrò ní ayé, kí lo máa wá ṣe nípa orúkọ ńlá rẹ?”+

10 Jèhófà dá Jóṣúà lóhùn pé: “Dìde! Kí ló dé tí o dojú bolẹ̀? 11 Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀. Wọ́n ti da májẹ̀mú mi+ tí mo pa láṣẹ pé kí wọ́n pa mọ́. Wọ́n kó lára ohun tí wọ́n máa pa run,+ wọ́n jí i,+ wọ́n sì lọ kó o pa mọ́ sáàárín ohun ìní wọn.+ 12 Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní lè dìde sí àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n á yí pa dà lẹ́yìn àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n á sì sá lọ, torí wọ́n ti di ohun tí a máa pa run. Mi ò ní wà pẹ̀lú yín mọ́, àfi tí ẹ bá run ohun tí a máa pa run tó wà láàárín yín.+ 13 Dìde, kí o sì sọ àwọn èèyàn náà di mímọ́!+ Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ sọ ara yín di mímọ́ torí ọ̀la, nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ohun tí a máa pa run wà ní àárín yín. Ẹ ò ní lè dìde sí àwọn ọ̀tá yín títí ẹ fi máa mú ohun tí a máa pa run kúrò láàárín yín. 14 Tó bá di àárọ̀, kí ẹ wá ní ẹ̀yà-ẹ̀yà, ẹ̀yà tí Jèhófà bá sì mú máa wá ní ìdílé-ìdílé, ìdílé tí Jèhófà bá sì mú+ máa wá ní agboolé-agboolé, àwọn ọkùnrin ní agbo ilé tí Jèhófà bá sì mú máa wá lọ́kọ̀ọ̀kan. 15 Ẹni tí a bá rí ohun tí a máa pa run lọ́wọ́ rẹ̀, ṣe la máa dáná sun ún,+ òun àti gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀, torí pé ó ti da májẹ̀mú+ Jèhófà àti pé ó ti hùwà tó ń dójú tini ní Ísírẹ́lì.”’”

16 Jóṣúà wá dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, ó ní kí Ísírẹ́lì wá ní ẹ̀yà-ẹ̀yà, a sì mú ẹ̀yà Júdà. 17 Ó ní kí àwọn ìdílé Júdà wá, a sì mú ìdílé àwọn ọmọ Síírà,+ lẹ́yìn náà, ó ní kí àwọn ọkùnrin ní ìdílé àwọn ọmọ Síírà wá lọ́kọ̀ọ̀kan, a sì mú Sábídì. 18 Níkẹyìn, ó ní kí àwọn ọkùnrin ní agboolé Sábídí wá lọ́kọ̀ọ̀kan, a sì mú Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Sábídí, ọmọ Síírà látinú ẹ̀yà Júdà.+ 19 Jóṣúà wá sọ fún Ákánì pé: “Ọmọ mi, jọ̀ọ́, bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí o sì jẹ́wọ́ fún un. Jọ̀ọ́, sọ ohun tí o ṣe fún mi. Má fi pa mọ́ fún mi.”

20 Ákánì dá Jóṣúà lóhùn pé: “Kí n sòótọ́, èmi ni mo ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ohun tí mo sì ṣe nìyí. 21 Nígbà tí mo rí ẹ̀wù oyè kan tó rẹwà láti Ṣínárì+ láàárín àwọn ẹrù ogun àti igba (200) ṣékélì* fàdákà àti wúrà gbọọrọ kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì, ọkàn mi fà sí i, mo sì kó o. Abẹ́ ilẹ̀ nínú àgọ́ mi ni mo kó o pa mọ́ sí, mo sì kó owó náà sábẹ́ rẹ̀.”

22 Ni Jóṣúà bá ní kí àwọn ìránṣẹ́ lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sì sáré lọ sínú àgọ́ náà, wọ́n rí ẹ̀wù náà nínú àgọ́ rẹ̀ níbi tó tọ́jú rẹ̀ sí, wọ́n sì rí owó náà lábẹ́ rẹ̀. 23 Wọ́n wá kó àwọn nǹkan náà kúrò nínú àgọ́ náà, wọ́n kó o wá sọ́dọ̀ Jóṣúà àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì kó o síwájú Jèhófà. 24 Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì wá mú Ákánì+ ọmọ Síírà, fàdákà náà, ẹ̀wù oyè náà àti wúrà gbọọrọ náà,+ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, akọ màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, agbo ẹran rẹ̀, àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Àfonífojì* Ákórì.+ 25 Jóṣúà sọ pé: “Kí ló dé tí o fa àjálù* bá wa?+ Jèhófà máa mú àjálù bá ọ lónìí.” Ni gbogbo Ísírẹ́lì bá sọ ọ́ lókùúta,+ lẹ́yìn náà, wọ́n dáná sun wọ́n.+ Bí wọ́n ṣe sọ gbogbo wọn lókùúta nìyẹn. 26 Wọ́n kó òkúta jọ pelemọ lé e lórí, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí dòní. Bí inú tó ń bí Jèhófà gidigidi ṣe rọlẹ̀ nìyẹn.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Àfonífojì Ákórì* títí dòní.

8 Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Má bẹ̀rù, má sì jáyà.+ Kó gbogbo ọkùnrin ogun, kí ẹ sì gòkè lọ bá ìlú Áì jà. Wò ó, mo ti fi ọba Áì lé yín lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀, ìlú rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀.+ 2 Ohun tí o ṣe sí Jẹ́ríkò àti ọba rẹ̀ gẹ́lẹ́ ni kí o ṣe sí Áì àti ọba rẹ̀,+ àmọ́ ẹ lè kó ẹrù ìlú náà àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ fún ara yín. Kí ẹ lúgọ sí ẹ̀yìn ìlú náà.”

3 Jóṣúà àti gbogbo ọkùnrin ogun wá lọ bá ìlú Áì jà. Jóṣúà yan àwọn jagunjagun tó lákíkanjú tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000), ó sì ní kí wọ́n lọ ní òru. 4 Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ wò ó, ẹ lúgọ sí ẹ̀yìn ìlú náà. Ẹ má jìnnà jù sí ìlú náà, kí gbogbo yín sì múra sílẹ̀. 5 Èmi àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú mi máa sún mọ́ ìlú náà, tí wọ́n bá sì jáde wá bá wa jà bíi ti tẹ́lẹ̀,+ a máa sá fún wọn. 6 Tí wọ́n bá ti tẹ̀ lé wa, a máa tàn wọ́n jìnnà sí ìlú náà, torí wọ́n á sọ pé, ‘Wọ́n ń sá fún wa bíi ti tẹ́lẹ̀.’+ A sì máa sá fún wọn. 7 Kí ẹ̀yin gbéra níbi tí ẹ lúgọ sí, kí ẹ sì gba ìlú náà; Jèhófà Ọlọ́run yín máa fi lé yín lọ́wọ́. 8 Gbàrà tí ẹ bá ti gba ìlú náà, kí ẹ dáná sun ún.+ Ohun tí Jèhófà sọ ni kí ẹ ṣe. Ẹ wò ó, mo ti pàṣẹ fún yín.”

9 Jóṣúà wá ní kí wọ́n lọ, wọ́n sì lọ sí ibi tí wọ́n máa lúgọ sí; wọ́n dúró sí àárín Bẹ́tẹ́lì àti Áì, lápá ìwọ̀ oòrùn Áì, Jóṣúà sì sun ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn náà mọ́jú.

10 Lẹ́yìn tí Jóṣúà dìde ní àárọ̀ kùtù, tó sì kó àwọn ọmọ ogun jọ,* òun àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì ṣáájú wọn lọ sí Áì. 11 Gbogbo àwọn ọkùnrin ogun+ tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gòkè lọ, wọ́n sì forí lé iwájú ìlú náà. Wọ́n pàgọ́ sí àríwá ìlú Áì, àfonífojì wà láàárín àwọn àti ìlú Áì. 12 Ní àkókò yẹn, ó ti ní kí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin lọ lúgọ+ sí àárín Bẹ́tẹ́lì+ àti Áì, lápá ìwọ̀ oòrùn ìlú náà. 13 Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ ogun náà pàgọ́ sí apá àríwá ìlú náà,+ àwọn ọmọ ogun tó wà lẹ́yìn pàgọ́ sí apá ìwọ̀ oòrùn ìlú náà,+ Jóṣúà sì lọ sí àárín àfonífojì* náà ní òru yẹn.

14 Gbàrà tí ọba Áì rí èyí, òun àtàwọn ọkùnrin ìlú náà yára jáde ní àárọ̀ kùtù láti bá Ísírẹ́lì jagun ní ibì kan tí wọ́n ti lè rí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú náà látòkè. Àmọ́ kò mọ̀ pé wọ́n ti lúgọ de òun ní ẹ̀yìn ìlú náà. 15 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Áì gbéjà kò wọ́n, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì sá gba ọ̀nà aginjù.+ 16 Ni wọ́n bá pe gbogbo àwọn tó wà nínú ìlú náà pé kí wọ́n jọ lépa wọn; bí wọ́n sì ṣe ń lé Jóṣúà ni Ísírẹ́lì ń tàn wọ́n jìnnà sí ìlú náà. 17 Kò sí ọkùnrin kankan ní ìlú Áì àti Bẹ́tẹ́lì tí kò jáde láti lépa Ísírẹ́lì. Wọ́n ṣí ìlú náà sílẹ̀ gbayawu, wọ́n sì lé Ísírẹ́lì lọ.

18 Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: “Na ọ̀kọ̀* tó wà lọ́wọ́ rẹ sí ìlú Áì,+ torí pé màá fi ìlú náà lé ọ lọ́wọ́.”+ Ni Jóṣúà bá na ọ̀kọ̀ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ sí ìlú náà. 19 Gbàrà tó na ọwọ́ rẹ̀, àwọn tó lúgọ yára dìde, wọ́n sáré wọnú ìlú náà, wọ́n sì gbà á. Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n dáná sun ìlú náà.+

20 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Áì wo ẹ̀yìn, tí wọ́n rí èéfín tó ń tinú ìlú náà lọ sókè, wọn ò ní okun láti sá lọ sí ibì kankan. Àwọn tó ti ń sá lọ sí ọ̀nà aginjù bá ṣẹ́rí pa dà, wọ́n sì kọjú sí àwọn tó ń lé wọn. 21 Nígbà tí Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì rí i pé àwọn tó lúgọ ti gba ìlú náà, tí wọ́n sì rí i tí èéfín ń tinú ìlú náà lọ sókè, wọ́n bá yíjú pa dà, wọ́n sì gbéjà ko àwọn ọmọ ogun Áì. 22 Àwọn yòókù jáde láti ìlú náà wá pàdé wọn, èyí mú kí àwọn ọmọ ogun Áì há sí àárín wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì wà ní iwájú àti ẹ̀yìn wọn, wọ́n pa wọ́n débi pé ẹnì kankan ò yè bọ́ tàbí kó sá mọ́ wọn lọ́wọ́.+ 23 Àmọ́ wọ́n mú ọba Áì+ láàyè, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Jóṣúà.

24 Lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì pa gbogbo àwọn tó ń gbé ìlú Áì tán níbi gbalasa, nínú aginjù tí wọ́n lé wọn lọ, tí wọ́n sì ti fi idà pa gbogbo wọn láìṣẹ́ ku ẹnì kan, gbogbo Ísírẹ́lì pa dà sí Áì, wọ́n sì fi idà pa á run. 25 Gbogbo àwọn tí wọ́n pa lọ́jọ́ yẹn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000), látorí ọkùnrin dórí obìnrin, gbogbo ará ìlú Áì. 26 Jóṣúà kò gbé ọwọ́ tó fi na ọ̀kọ̀+ náà wálẹ̀ títí ó fi pa gbogbo àwọn tó ń gbé ìlú Áì run.+ 27 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó ẹran ọ̀sìn àti ẹrù ìlú náà fún ara wọn, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà.+

28 Jóṣúà wá dáná sun ìlú Áì, ó sọ ọ́ di òkìtì àwókù,+ bó sì ṣe wà nìyẹn títí dòní. 29 Ó gbé ọba Áì kọ́ sórí òpó igi* títí di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn sì ti fẹ́ wọ̀, Jóṣúà pàṣẹ pé kí wọ́n sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ látorí òpó igi.+ Wọ́n sì jù ú síbi àbáwọlé ẹnubodè ìlú náà, wọ́n kó òkúta lé e lórí pelemọ, ó sì wà níbẹ̀ títí dòní.

30 Ìgbà yẹn ni Jóṣúà mọ pẹpẹ kan sí Òkè Ébálì+ fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, 31 bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bó sì ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Òfin+ Mósè pé kó jẹ́: “Pẹpẹ tí wọ́n fi àwọn odindi òkúta ṣe, tí wọn ò fi irinṣẹ́ èyíkéyìí gbẹ́.”+ Wọ́n rú àwọn ẹbọ sísun àtàwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ lórí rẹ̀ sí Jèhófà.+

32 Lẹ́yìn náà, ó kọ ẹ̀dà Òfin+ tí Mósè kọ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ sára àwọn òkúta náà níbẹ̀. 33 Gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn àgbààgbà wọn, àwọn olórí àtàwọn adájọ́ wọn dúró sí ẹ̀gbẹ́ méjèèjì Àpótí náà, níwájú àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, tí wọ́n ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà. Àwọn àjèjì àtàwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà wà níbẹ̀.+ Ìdajì wọn dúró síwájú Òkè Gérísímù, ìdajì tó kù sì wà níwàjú Òkè Ébálì+ (bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe pa á láṣẹ tẹ́lẹ̀),+ láti súre fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì. 34 Lẹ́yìn náà, ó ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú Òfin+ náà sókè, àwọn ìbùkún+ àti àwọn ègún+ tó wà nínú rẹ̀, bí wọ́n ṣe kọ gbogbo rẹ̀ sínú ìwé Òfin náà. 35 Kò sí ọ̀rọ̀ kankan nínú gbogbo ohun tí Mósè pa láṣẹ tí Jóṣúà kò kà sókè níwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì,+ títí kan àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé àtàwọn àjèjì+ tó ń gbé* láàárín wọn.+

9 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì+ gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, àwọn tó wà ní agbègbè olókè, ní Ṣẹ́fẹ́là, ní gbogbo etí Òkun Ńlá*+ àti níwájú Lẹ́bánónì, ìyẹn àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àtàwọn ará Jébúsì,+ 2 wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti bá Jóṣúà àti Ísírẹ́lì jà.+

3 Àwọn tó ń gbé Gíbíónì+ náà gbọ́ ohun tí Jóṣúà ṣe sí Jẹ́ríkò+ àti Áì.+ 4 Torí náà, wọ́n dá ọgbọ́n kan, wọ́n kó oúnjẹ sínú àwọn àpò tó ti gbó, wọ́n sì gbé e sórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, pẹ̀lú awọ tí wọ́n ń rọ wáìnì sí, tó ti gbó, tó sì ti bẹ́, àmọ́ tí wọ́n ti rán; 5 wọ́n tún wọ bàtà tó ti gbó, tí wọ́n sì ti lẹ̀, aṣọ ọrùn wọn náà ti gbó. Gbogbo búrẹ́dì tí wọ́n gbé dání ti gbẹ, ó sì ti ń rún. 6 Wọ́n wá lọ bá Jóṣúà níbi tí Ísírẹ́lì pàgọ́ sí ní Gílígálì,+ wọ́n sì sọ fún òun àtàwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé: “Ọ̀nà jíjìn la ti wá. Ẹ wá bá wa dá májẹ̀mú.” 7 Àmọ́ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fún àwọn Hífì+ pé: “Bóyá tòsí wa lẹ tiẹ̀ ń gbé. Báwo la ṣe máa bá yín dá májẹ̀mú?”+ 8 Wọ́n dá Jóṣúà lóhùn pé: “Ìránṣẹ́* rẹ ni wá.”

Jóṣúà wá bi wọ́n pé: “Ta ni yín, ibo lẹ sì ti wá?” 9 Wọ́n fèsì pé: Ọ̀nà tó jìn gan-an ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ti wá,+ torí a gbọ́ nípa orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, òkìkí rẹ̀ kàn dé ọ̀dọ̀ wa, a sì ti gbọ́ nípa gbogbo ohun tó ṣe ní Íjíbítì+ 10 àti gbogbo ohun tó ṣe sí àwọn ọba Ámórì méjèèjì tí wọ́n wà ní òdìkejì* Jọ́dánì, ìyẹn Síhónì+ ọba Hẹ́ṣíbónì àti Ógù+ ọba Báṣánì, tó wà ní Áṣítárótì. 11 Torí náà, àwọn àgbààgbà wa àti gbogbo àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ wa sọ fún wa pé, ‘Ẹ kó oúnjẹ tí ẹ máa jẹ lẹ́nu ìrìn àjò yín dání, kí ẹ sì lọ bá wọn. Kí ẹ sọ fún wọn pé: “A máa di ìránṣẹ́ yín;+ kí ẹ bá wa dá májẹ̀mú.”’+ 12 Búrẹ́dì tí a kó dání yìí ṣì gbóná lọ́jọ́ tí a kúrò ní ilé wa láti wá bá yín níbí. Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, ó ti gbẹ, ó sì ti ń rún.+ 13 Àwọn awọ yìí ṣì tuntun nígbà tí a rọ wáìnì sínú wọn, àmọ́ wọ́n ti bẹ́ báyìí.+ Aṣọ àti bàtà wa sì ti gbó torí pé ọ̀nà tí a rìn jìn gan-an.”

14 Ni àwọn ọkùnrin náà bá gbà lára oúnjẹ wọn,* àmọ́ wọn ò wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.+ 15 Jóṣúà bá wọn ṣàdéhùn àlàáfíà,+ ó sì bá wọn dá májẹ̀mú pé òun máa dá ẹ̀mí wọn sí, ohun tí àwọn ìjòyè àpéjọ náà sì búra fún wọn nìyẹn.+

16 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n bá wọn dá májẹ̀mú, wọ́n gbọ́ pé tòsí wọn ni wọ́n ń gbé, ọ̀nà wọn ò sì jìn rárá. 17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá gbéra, wọ́n sì dé àwọn ìlú wọn ní ọjọ́ kẹta; àwọn ìlú wọn ni Gíbíónì,+ Kéfírà, Béérótì àti Kiriati-jéárímù.+ 18 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbéjà kò wọ́n, torí pé àwọn ìjòyè àpéjọ náà ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra+ fún wọn. Gbogbo àpéjọ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí àwọn ìjòyè náà. 19 Ni gbogbo àwọn ìjòyè náà bá sọ fún gbogbo àpéjọ náà pé: “A ò lè pa wọ́n lára torí pé a ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún wọn. 20 Ohun tí a máa ṣe nìyí: A máa dá ẹ̀mí wọn sí, kí ìbínú má bàa wá sórí wa torí ìbúra tí a ṣe fún wọn.”+ 21 Àwọn ìjòyè náà sì sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká dá ẹ̀mí wọn sí, àmọ́ kí wọ́n máa bá wa ṣẹ́gi, kí wọ́n sì máa pọnmi fún gbogbo àpéjọ náà.” Ìlérí tí àwọn ìjòyè náà ṣe fún wọn nìyẹn.

22 Lẹ́yìn náà, Jóṣúà pè wọ́n, ó sì sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ tàn wá, tí ẹ sọ pé, ‘Ibi tó jìnnà gan-an sí yín la ti wá,’ nígbà tó jẹ́ pé àárín wa níbí lẹ̀ ń gbé?+ 23 Ẹni ègún ni yín látòní lọ,+ ẹrú ni ẹ ó sì máa jẹ́, ẹ̀ẹ́ máa ṣẹ́gi, ẹ̀ẹ́ sì máa pọnmi fún ilé Ọlọ́run mi.” 24 Wọ́n dá Jóṣúà lóhùn pé: “Torí àwa ìránṣẹ́ rẹ gbọ́ ọ kedere pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ láti fún yín ní gbogbo ilẹ̀ náà, pé òun máa pa gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀ run kúrò níwájú yín.+ Ìyẹn ló mú kí ẹ̀rù yín bà wá,+ torí a ò fẹ́ kí ẹ̀mí* wa lọ sí i la fi ṣe bẹ́ẹ̀.+ 25 Àfi kí o ṣàánú wa báyìí.* Ohunkóhun tí o bá rò pé ó tọ́, tó sì dáa ni kí o ṣe fún wa.” 26 Ohun tó sì ṣe sí wọn nìyẹn; ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn ò sì pa wọ́n. 27 Àmọ́ ọjọ́ yẹn ni Jóṣúà sọ wọ́n di aṣẹ́gi àti àwọn tí á máa pọnmi fún àpéjọ náà+ àti pẹpẹ Jèhófà ní ibi tí Ó bá yàn,+ iṣẹ́ tí wọ́n sì ń ṣe títí di òní nìyẹn.+

10 Gbàrà tí Adoni-sédékì ọba Jerúsálẹ́mù gbọ́ pé Jóṣúà ti gba Áì, tó sì ti pa á run, tó ṣe ohun tó ṣe fún Jẹ́ríkò àti ọba rẹ̀+ gẹ́lẹ́ sí Áì àti ọba rẹ̀+ àti bí àwọn tó ń gbé Gíbíónì ṣe bá Ísírẹ́lì ṣàdéhùn+ àlàáfíà, tí wọ́n sì wá ń gbé ní àárín wọn, 2 ẹ̀rù bà á gidigidi,+ torí pé ìlú ńlá ni Gíbíónì, ó dà bí ọ̀kan lára àwọn ìlú ọba. Ó tóbi ju ìlú Áì lọ,+ jagunjagun sì ni gbogbo àwọn ọkùnrin ibẹ̀. 3 Adoni-sédékì ọba Jerúsálẹ́mù wá ránṣẹ́ sí Hóhámù ọba Hébúrónì,+ Pírámù ọba Jámútì, Jáfíà ọba Lákíṣì àti Débírì ọba Ẹ́gílónì+ pé: 4 “Ẹ wá ràn mí lọ́wọ́, ká lè jọ gbógun ja Gíbíónì, torí ó ti bá Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àdéhùn àlàáfíà.”+ 5 Ni àwọn ọba Ámórì+ márààrún bá kóra jọ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun wọn, ìyẹn ọba Jerúsálẹ́mù, ọba Hébúrónì, ọba Jámútì, ọba Lákíṣì àti ọba Ẹ́gílónì, wọ́n sì lọ pàgọ́ ti Gíbíónì láti bá a jà.

6 Àwọn ará Gíbíónì wá ránṣẹ́ sí Jóṣúà ní ibùdó tó wà ní Gílígálì+ pé: “Má fi àwa ẹrú rẹ sílẹ̀.*+ Tètè máa bọ̀! Wá gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́! Gbogbo àwọn ọba Ámórì láti agbègbè olókè ti kóra jọ láti bá wa jà.” 7 Jóṣúà bá gbéra láti Gílígálì, òun àti gbogbo ọkùnrin ogun pẹ̀lú àwọn jagunjagun tó lákíkanjú.+

8 Jèhófà sì sọ fún Jóṣúà pé: “Má bẹ̀rù wọn,+ torí mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.+ Ìkankan nínú wọn ò ní lè dojú kọ ọ́.”+ 9 Òjijì ni Jóṣúà dé láti bá wọn jà lẹ́yìn tó ti fi gbogbo òru rìn wá láti Gílígálì. 10 Jèhófà da àárín wọn rú níwájú Ísírẹ́lì,+ wọ́n sì pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ ní Gíbíónì, wọ́n lé wọn gba ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gòkè lọ sí Bẹti-hórónì, wọ́n sì ń pa wọ́n títí lọ dé Ásékà àti Mákédà. 11 Bí wọ́n ṣe ń sá fún Ísírẹ́lì, tí wọ́n sì wà níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Bẹti-hórónì, Jèhófà rọ̀jò òkúta yìnyín ńláńlá lé wọn lórí láti ọ̀run, ó ń rọ̀ lé wọn lórí títí dé Ásékà, wọ́n sì ṣègbé. Kódà, àwọn tí yìnyín náà pa pọ̀ ju àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa lọ.

12 Lọ́jọ́ tí Jèhófà ṣẹ́gun àwọn Ámórì níṣojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìgbà yẹn ni Jóṣúà sọ fún Jèhófà níṣojú Ísírẹ́lì pé:

“Oòrùn, dúró sójú kan+ lórí Gíbíónì,+

Àti òṣùpá, lórí Àfonífojì* Áíjálónì!”

13 Bí oòrùn ṣe dúró sójú kan nìyẹn, òṣùpá ò sì kúrò títí orílẹ̀-èdè náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ṣebí wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé Jáṣárì?+ Oòrùn dúró sójú kan ní àárín ojú ọ̀run, kò sì tètè wọ̀ fún nǹkan bí odindi ọjọ́ kan. 14 Kò tíì sí ọjọ́ kankan bí ọjọ́ yìí, ṣáájú rẹ̀ tàbí lẹ́yìn rẹ̀, tí Jèhófà fetí sí ohùn èèyàn,+ torí Jèhófà ń jà fún Ísírẹ́lì.+

15 Lẹ́yìn náà, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì pa dà sí Gílígálì tí wọ́n pàgọ́ sí.+

16 Àmọ́ àwọn ọba márààrún sá lọ, wọ́n sì lọ fara pa mọ́ sí inú ihò àpáta ní Mákédà.+ 17 Àwọn kan wá sọ fún Jóṣúà pé: “A ti rí àwọn ọba márààrún tí wọ́n fara pa mọ́ sí inú ihò àpáta ní Mákédà.”+ 18 Jóṣúà wá sọ pé: “Ẹ yí àwọn òkúta ńlá sí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin tí á máa ṣọ́ wọn. 19 Àmọ́ ẹ̀yin tó kù ò gbọ́dọ̀ dáwọ́ dúró. Ẹ lé àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ sì máa ṣá wọn balẹ̀ láti ẹ̀yìn.+ Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n wọnú àwọn ìlú wọn, torí Jèhófà Ọlọ́run yín ti fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”

20 Lẹ́yìn tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ, débi pé wọ́n pa wọ́n run, àfi àwọn kan tó sá lọ sí àwọn ìlú olódi, 21 gbogbo àwọn èèyàn náà pa dà sọ́dọ̀ Jóṣúà ní ibùdó tó wà ní Mákédà, ohunkóhun ò sì ṣe wọ́n. Kò sẹ́ni tó gbójúgbóyà láti sọ̀rọ̀ kankan* sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 22 Jóṣúà wá sọ pé: “Ẹ ṣí ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba márààrún jáde látinú ihò wá bá mi.” 23 Wọ́n mú àwọn ọba márààrún yìí jáde wá bá a látinú ihò náà: ọba Jerúsálẹ́mù, ọba Hébúrónì, ọba Jámútì, ọba Lákíṣì àti ọba Ẹ́gílónì.+ 24 Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba yìí dé ọ̀dọ̀ Jóṣúà, ó pe gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì, ó sì sọ fún àwọn ọ̀gágun nínú àwọn ọkùnrin ogun tó bá a lọ pé: “Ẹ bọ́ síwájú. Ẹ gbé ẹsẹ̀ yín lé ẹ̀yìn ọrùn àwọn ọba yìí.” Wọ́n wá bọ́ síwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ wọn lé ẹ̀yìn ọrùn wọn.+ 25 Lẹ́yìn náà, Jóṣúà sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà.+ Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára, torí ohun tí Jèhófà máa ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí ẹ̀ ń bá jà nìyí.”+

26 Jóṣúà wá ṣá wọn balẹ̀, ó sì pa wọ́n, ó gbé wọn kọ́ sórí òpó* márùn-ún, wọ́n sì wà lórí òpó náà títí di ìrọ̀lẹ́. 27 Nígbà tí oòrùn wọ̀, Jóṣúà pàṣẹ pé kí wọ́n gbé wọn kúrò lórí òpó+ kí wọ́n sì jù wọ́n sí inú ihò àpáta tí wọ́n fara pa mọ́ sí. Wọ́n wá yí àwọn òkúta ńlá sí ẹnu ihò náà, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí di òní olónìí.

28 Jóṣúà gba Mákédà+ ní ọjọ́ yẹn, ó sì fi idà pa á run. Ó pa ọba rẹ̀ àti gbogbo àwọn* tó ń gbé ibẹ̀ run, kò ṣẹ́ ẹnì kankan kù.+ Ohun tó ṣe sí ọba Jẹ́ríkò gẹ́lẹ́ ló ṣe sí ọba Mákédà.+

29 Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì wá kúrò ní Mákédà lọ sí Líbínà, wọ́n sì bá Líbínà+ jà. 30 Jèhófà tún fi ìlú náà àti ọba rẹ̀+ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, wọ́n sì fi idà pa ìlú náà run àti gbogbo àwọn* tó ń gbé ibẹ̀, wọn ò ṣẹ́ ẹnì kankan kù níbẹ̀. Ohun tí wọ́n ṣe sí ọba Jẹ́ríkò+ gẹ́lẹ́ ni wọ́n ṣe sí ọba ìlú náà.

31 Lẹ́yìn náà, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì kúrò ní Líbínà lọ sí Lákíṣì,+ wọ́n pàgọ́ tì í, wọ́n sì bá a jà. 32 Jèhófà fi Lákíṣì lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, wọ́n sì gbà á ní ọjọ́ kejì. Wọ́n fi idà pa ìlú náà run àti gbogbo àwọn* tó ń gbé ibẹ̀,+ bí wọ́n ṣe ṣe sí Líbínà gẹ́lẹ́.

33 Hórámù ọba Gésérì+ wá lọ ran Lákíṣì lọ́wọ́, àmọ́ Jóṣúà pa òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ láìku ẹnì kan.

34 Lẹ́yìn náà, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì kúrò ní Lákíṣì lọ sí Ẹ́gílónì,+ wọ́n pàgọ́ tì í, wọ́n sì bá a jà. 35 Wọ́n gbà á ní ọjọ́ yẹn, wọ́n sì fi idà pa á run. Wọ́n pa gbogbo àwọn* tó ń gbé ibẹ̀ run lọ́jọ́ yẹn, bí wọ́n ṣe ṣe sí Lákíṣì gẹ́lẹ́.+

36 Lẹ́yìn náà, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì kúrò ní Ẹ́gílónì lọ sí Hébúrónì,+ wọ́n sì bá a jà. 37 Wọ́n gbà á, wọ́n sì fi idà pa á run, pẹ̀lú ọba rẹ̀, àwọn ìlú rẹ̀ àti gbogbo àwọn* tó ń gbé ibẹ̀, wọn ò ṣẹ́ ẹnì kankan kù. Ó pa Hébúrónì àti gbogbo àwọn* tó ń gbé ibẹ̀ run bó ṣe ṣe sí Ẹ́gílónì gẹ́lẹ́.

38 Níkẹyìn, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì ṣẹ́rí pa dà, wọ́n sì lọ bá Débírì+ jà. 39 Ó gba ibẹ̀, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú rẹ̀, wọ́n sì fi idà pa wọ́n, wọ́n pa gbogbo àwọn* tó ń gbé ibẹ̀ run,+ wọn ò ṣẹ́ ẹnì kankan kù.+ Ohun tó ṣe sí Hébúrónì àti Líbínà àti ọba rẹ̀ náà ló ṣe sí Débírì àti ọba rẹ̀.

40 Jóṣúà ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ tó wà ní agbègbè olókè, Négébù, Ṣẹ́fẹ́là,+ àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àti gbogbo ọba wọn, kò ṣẹ́ ẹnì kankan kù; ó pa gbogbo ohun eléèémí run,+ bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣe pa á láṣẹ gẹ́lẹ́.+ 41 Jóṣúà ṣẹ́gun wọn láti Kadeṣi-báníà+ títí dé Gásà+ àti gbogbo ilẹ̀ Góṣénì+ títí dé Gíbíónì.+ 42 Ìgbà kan náà ni Jóṣúà ṣẹ́gun àwọn ọba yìí àti gbogbo ilẹ̀ wọn, torí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ló ń jà fún Ísírẹ́lì.+ 43 Lẹ́yìn náà, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì pa dà sí ibùdó ní Gílígálì.+

11 Gbàrà tí Jábínì ọba Hásórì gbọ́ nípa rẹ̀, ó ránṣẹ́ sí Jóbábù ọba Mádónì,+ sí ọba Ṣímúrónì, ọba Ákíṣáfù,+ 2 àwọn ọba agbègbè olókè tó wà ní apá àríwá, àwọn tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀* apá gúúsù Kínérétì, àwọn tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là àti ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Dórì+ ní ìwọ̀ oòrùn, 3 àwọn ọmọ Kénáánì+ lápá ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn ará Jébúsì ní agbègbè olókè àti àwọn Hífì+ ní ìsàlẹ̀ Hámónì+ ní ilẹ̀ Mísípà. 4 Wọ́n kó gbogbo ọmọ ogun wọn jáde, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun. 5 Gbogbo àwọn ọba yìí ṣe àdéhùn láti pàdé, wọ́n wá, wọ́n sì jọ pàgọ́ síbi omi Mérómù láti bá Ísírẹ́lì jà.

6 Torí náà, Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́,+ torí ní ìwòyí ọ̀la, màá fi gbogbo wọn lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ láti pa wọ́n. Kí o já iṣan ẹsẹ̀*+ àwọn ẹṣin wọn, kí o sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn.” 7 Jóṣúà àti gbogbo ọkùnrin ogun wá gbéjà kò wọ́n lójijì lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi Mérómù. 8 Jèhófà fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́,+ wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n lé wọn títí dé Sídónì Ńlá+ àti Misirefoti-máímù+ àti Àfonífojì Mísípè lápá ìlà oòrùn, wọ́n sì pa wọ́n láìku ẹnì kankan.+ 9 Jóṣúà wá ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un sí wọn; ó já iṣan ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin wọn, ó sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn.+

10 Lẹ́yìn náà, Jóṣúà pa dà, ó sì gba Hásórì, o fi idà pa ọba rẹ̀,+ torí pé Hásórì ni olórí gbogbo àwọn ìlú yìí tẹ́lẹ̀. 11 Wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn* tó ń gbé ibẹ̀ run pátápátá.+ Wọn ò dá ohun eléèémí kankan sí.+ Lẹ́yìn náà, ó dáná sun Hásórì. 12 Jóṣúà gba gbogbo ìlú àwọn ọba yìí, ó sì fi idà ṣẹ́gun gbogbo ọba wọn.+ Ó pa wọ́n run,+ bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe pa á láṣẹ. 13 Àmọ́ Ísírẹ́lì ò dáná sun ìkankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkìtì, àfi Hásórì; òun nìkan ni Jóṣúà dáná sun. 14 Gbogbo ẹrù àwọn ìlú yìí àti ẹran ọ̀sìn wọn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó fún ara wọn.+ Àmọ́ wọ́n fi idà pa gbogbo èèyàn títí wọ́n fi pa gbogbo wọn run.+ Wọn ò dá ẹnikẹ́ni tó ń mí sí.+ 15 Bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Mósè ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà,+ Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè ni Jóṣúà ṣe láìṣẹ́ ìkankan kù.+

16 Jóṣúà ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ yìí, agbègbè olókè, gbogbo Négébù,+ gbogbo ilẹ̀ Góṣénì, Ṣẹ́fẹ́là,+ Árábà+ àti agbègbè olókè Ísírẹ́lì àti Ṣẹ́fẹ́là rẹ̀,* 17 láti Òkè Hálákì, tó lọ dé Séírì àti títí lọ dé Baali-gádì,+ ní Àfonífojì Lẹ́bánónì, ní ìsàlẹ̀ Òkè Hámónì,+ ó mú gbogbo ọba wọn, ó ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n. 18 Ó ṣe díẹ̀ tí Jóṣúà fi bá gbogbo àwọn ọba yìí jagun. 19 Kò sí ìlú kankan tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rẹ́ àfi àwọn Hífì tó ń gbé ní Gíbíónì.+ Gbogbo àwọn yòókù ni wọ́n bá jà tí wọ́n sì ṣẹ́gun wọn.+ 20 Jèhófà fàyè gbà á kí ọkàn wọn le,+ tí wọ́n fi bá Ísírẹ́lì jagun, kó lè pa wọ́n run láì ṣojú àánú sí wọn rárá.+ Ìparun tọ́ sí wọn, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.+

21 Ìgbà yẹn ni Jóṣúà pa àwọn Ánákímù+ run kúrò ní agbègbè olókè, ní Hébúrónì, Débírì, Ánábù àti gbogbo agbègbè olókè Júdà àti gbogbo agbègbè olókè Ísírẹ́lì. Jóṣúà pa àwọn àtàwọn ìlú wọn run.+ 22 Ánákímù kankan ò ṣẹ́ kù ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;+ Gásà,+ Gátì+ àti Áṣídódì+ nìkan ni wọ́n ṣẹ́ kù sí. 23 Jóṣúà wá gba gbogbo ilẹ̀ náà, bí Jèhófà ṣe ṣèlérí fún Mósè,+ Jóṣúà sì fi ṣe ogún fún Ísírẹ́lì, bí ìpín wọn, pé kí wọ́n pín in láàárín àwọn ẹ̀yà wọn.+ Ogun sì dáwọ́ dúró ní ilẹ̀ náà.+

12 Àwọn ọba ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun nìyí, tí wọ́n gba ilẹ̀ wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, láti Àfonífojì Áánónì+ dé Òkè Hámónì+ àti gbogbo Árábà lápá ìlà oòrùn:+ 2 Síhónì+ ọba àwọn Ámórì, tó ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì, tó sì ń jọba láti Áróérì,+ tó wà létí Àfonífojì Áánónì+ àti láti àárín àfonífojì náà àti ìdajì Gílíádì títí dé Àfonífojì Jábókù, ààlà àwọn ọmọ Ámónì. 3 Ó tún jọba lé Árábà títí dé Òkun Kínérétì*+ lápá ìlà oòrùn títí dé Òkun Árábà, Òkun Iyọ̀,* ní ìlà oòrùn sí Bẹti-jẹ́ṣímótì àti sí apá gúúsù lábẹ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.+

4 Ó tún gba ilẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Réfáímù+ tó kẹ́yìn, tó ń gbé ní Áṣítárótì àti Édíréì, 5 tó sì jọba ní Òkè Hámónì, ní Sálékà àti gbogbo Báṣánì,+ títí lọ dé ààlà àwọn ará Géṣúrì àti àwọn ará Máákátì+ àti ìdajì Gílíádì, títí dé ilẹ̀ Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì.+

6 Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun wọn,+ Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà sì fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ilẹ̀ àwọn ọba yìí pé kó di tiwọn.+

7 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọba ilẹ̀ tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun lápá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì, láti Baali-gádì,+ ní Àfonífojì Lẹ́bánónì+ títí dé Òkè Hálákì,+ tó lọ dé Séírì,+ tí Jóṣúà wá fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ àwọn ọba náà pé kó di tiwọn, bí ìpín wọn,+ 8 ní agbègbè olókè, ní Ṣẹ́fẹ́là, Árábà, àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, ní aginjù àti ní Négébù,+ ìyẹn ilẹ̀ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì:+

 9 Ọba Jẹ́ríkò,+ ọ̀kan; ọba Áì,+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bẹ́tẹ́lì, ọ̀kan;

10 ọba Jerúsálẹ́mù, ọ̀kan; ọba Hébúrónì,+ ọ̀kan;

11 ọba Jámútì, ọ̀kan; ọba Lákíṣì, ọ̀kan;

12 ọba Ẹ́gílónì, ọ̀kan; ọba Gésérì,+ ọ̀kan;

13 ọba Débírì,+ ọ̀kan; ọba Gédérì, ọ̀kan;

14 ọba Hóómà, ọ̀kan; ọba Árádì, ọ̀kan;

15 ọba Líbínà,+ ọ̀kan; ọba Ádúlámù, ọ̀kan;

16 ọba Mákédà,+ ọ̀kan; ọba Bẹ́tẹ́lì,+ ọ̀kan;

17 ọba Tápúà, ọ̀kan; ọba Héfà, ọ̀kan;

18 ọba Áfékì, ọ̀kan; ọba Lasiṣárónì, ọ̀kan;

19 ọba Mádónì, ọ̀kan; ọba Hásórì,+ ọ̀kan;

20 ọba Ṣimuroni-mérónì, ọ̀kan; ọba Ákíṣáfù, ọ̀kan;

21 ọba Táánákì, ọ̀kan; ọba Mẹ́gídò, ọ̀kan;

22 ọba Kédéṣì, ọ̀kan; ọba Jókínéámù+ ní Kámẹ́lì, ọ̀kan;

23 ọba Dórì ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Dórì,+ ọ̀kan; ọba Góíímù ní Gílígálì, ọ̀kan;

24 ọba Tírísà, ọ̀kan; gbogbo àwọn ọba náà jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31).

13 Ní báyìí, Jóṣúà ti darúgbó, ó sì ti lọ́jọ́ lórí.+ Jèhófà sọ fún un pé: “O ti darúgbó, o sì ti lọ́jọ́ lórí; àmọ́ ẹ ò tíì gba* èyí tó pọ̀ jù nínú ilẹ̀ náà. 2 Àwọn ilẹ̀ tó ṣẹ́ kù nìyí:+ gbogbo ilẹ̀ àwọn Filísínì àti ti gbogbo àwọn ará Géṣúrì+ 3 (láti ẹ̀ka odò Náílì* tó wà ní ìlà oòrùn* Íjíbítì títí dé ààlà Ẹ́kírónì lọ sí àríwá, tí wọ́n máa ń pè ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì)+ pẹ̀lú ilẹ̀ àwọn alákòóso Filísínì márààrún,+ ìyẹn àwọn ará Gásà, àwọn ará Áṣídódì,+ àwọn ará Áṣíkẹ́lónì,+ àwọn ará Gátì+ àti àwọn ará Ẹ́kírónì;+ ilẹ̀ àwọn Áfímù+ 4 lọ sí apá gúúsù; gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì; Méárà, tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Sídónì,+ títí lọ dé Áfékì, dé ààlà àwọn Ámórì; 5 ilẹ̀ àwọn ará Gébálì+ àti gbogbo Lẹ́bánónì lápá ìlà oòrùn, láti Baali-gádì ní ìsàlẹ̀ Òkè Hámónì títí dé Lebo-hámátì;*+ 6 gbogbo àwọn tó ń gbé agbègbè olókè láti Lẹ́bánónì+ lọ dé Misirefoti-máímù;+ àti gbogbo àwọn ọmọ Sídónì.+ Mo máa lé wọn kúrò* níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Kí o ṣáà rí i pé o pín in fún Ísírẹ́lì pé kó jẹ́ ogún wọn, bí mo ṣe pa á láṣẹ fún ọ.+ 7 Kí o pín ilẹ̀ yìí fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè pé kó jẹ́ ogún wọn.”+

8 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà tó kù, wá gba ogún wọn tí Mósè fún wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe fún wọn:+ 9 láti Áróérì,+ tó wà létí Àfonífojì Áánónì+ àti ìlú tó wà láàárín àfonífojì náà àti gbogbo ilẹ̀ tó tẹ́jú* ní Médébà títí dé Díbónì; 10 àti gbogbo ìlú Síhónì ọba àwọn Ámórì, tó jọba ní Hẹ́ṣíbónì, títí dé ààlà àwọn ọmọ Ámónì;+ 11 pẹ̀lú Gílíádì àti ilẹ̀ àwọn ará Géṣúrì àti tàwọn ará Máákátì+ àti gbogbo Òkè Hámónì pẹ̀lú gbogbo Báṣánì+ títí lọ dé Sálékà;+ 12 gbogbo ilẹ̀ ọba Ógù ní Báṣánì, tó jọba ní Áṣítárótì àti Édíréì. (Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Réfáímù+ tó kẹ́yìn.) Mósè ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn kúrò.*+ 13 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lé+ àwọn ará Géṣúrì àti àwọn ará Máákátì kúrò,* torí àwọn Géṣúrì àti Máákátì ṣì wà láàárín Ísírẹ́lì títí di òní yìí.

14 Ẹ̀yà àwọn ọmọ Léfì nìkan ni kò pín ogún fún.+ Àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún wọn,+ bó ṣe ṣèlérí fún wọn.+

15 Mósè pín ogún fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní ìdílé-ìdílé, 16 ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Áróérì, tó wà létí Àfonífojì Áánónì àti ìlú tó wà láàárín àfonífojì náà pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ tó tẹ́jú lẹ́gbẹ̀ẹ́ Médébà; 17 Hẹ́ṣíbónì àti gbogbo ìlú rẹ̀+ tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú, Díbónì, Bamoti-báálì, Bẹti-baali-méónì,+ 18 Jáhásì,+ Kédémótì,+ Mẹ́fáátì,+ 19 Kiriátáímù, Síbúmà,+ Sereti-ṣáhà lórí òkè tó wà ní àfonífojì,* 20 Bẹti-péórì, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà,+ Bẹti-jẹ́ṣímótì,+ 21 gbogbo ìlú tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú àti gbogbo ilẹ̀ Síhónì ọba àwọn Ámórì, tó jọba ní Hẹ́ṣíbónì.+ Mósè ṣẹ́gun òun+ àtàwọn ìjòyè Mídíánì, ìyẹn Éfì, Rékémù, Súúrì, Húrì àti Rébà,+ àwọn ọba tó wà lábẹ́ Síhónì, tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà. 22 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa Báláámù+ ọmọ Béórì, tó jẹ́ woṣẹ́woṣẹ́+ pẹ̀lú àwọn yòókù tí wọ́n pa. 23 Jọ́dánì ni ààlà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì; ilẹ̀ yìí sì ni ogún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní ìdílé-ìdílé, pẹ̀lú àwọn ìlú náà àtàwọn ìgbèríko wọn.

24 Bákan náà, Mósè pín ogún fún ẹ̀yà Gádì, àwọn ọmọ Gádì ní ìdílé-ìdílé, 25 ara ilẹ̀ wọn sì ni Jásérì+ àti gbogbo ìlú tó wà ní Gílíádì pẹ̀lú ìdajì ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì+ títí dé Áróérì, èyí tó dojú kọ Rábà;+ 26 láti Hẹ́ṣíbónì+ dé Ramati-mísípè àti Bẹ́tónímù àti láti Máhánáímù+ títí dé ààlà Débírì; 27 àti ní àfonífojì,* Bẹti-hárámù, Bẹti-nímírà,+ Súkótù+ àti Sáfónì, èyí tó kù nínú ilẹ̀ Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì,+ tí Jọ́dánì jẹ́ ààlà rẹ̀ láti apá ìsàlẹ̀ Òkun Kínérétì*+ lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì. 28 Ogún àwọn ọmọ Gádì nìyí ní ìdílé-ìdílé, pẹ̀lú àwọn ìlú náà àtàwọn ìgbèríko wọn.

29 Yàtọ̀ síyẹn, Mósè pín ogún fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ìdajì nínú ẹ̀yà Mánásè ní ìdílé-ìdílé.+ 30 Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Máhánáímù+ tó fi mọ́ gbogbo Báṣánì, gbogbo ilẹ̀ Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo abúlé Jáírì+ tí wọ́n pàgọ́ sí ní Báṣánì, ó jẹ́ ọgọ́ta (60) ìlú. 31 Ìdajì Gílíádì pẹ̀lú Áṣítárótì àti Édíréì,+ àwọn ìlú tó wà ní ilẹ̀ ọba Ógù ní Báṣánì, di ti àwọn ọmọ Mákírù,+ ọmọ Mánásè, ìyẹn ìdajì àwọn ọmọ Mákírù ní ìdílé-ìdílé.

32 Èyí ni ogún tí Mósè pín fún wọn ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù ní ìkọjá Jọ́dánì, lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò.+

33 Àmọ́ Mósè ò fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Léfì ní ogún kankan.+ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún wọn, bó ṣe ṣèlérí fún wọn.+

14 Èyí ni ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà ní ilẹ̀ Kénáánì, èyí tí àlùfáà Élíásárì àti Jóṣúà ọmọ Núnì àtàwọn olórí agbo ilé àwọn ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún wọn pé kí wọ́n jogún.+ 2 Kèké ni wọ́n fi pín ogún+ fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án àtààbọ̀ náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+ 3 Mósè ti pín ogún fún ẹ̀yà méjì àtààbọ̀ yòókù ní òdìkejì* Jọ́dánì,+ àmọ́ kò pín ogún kankan fún àwọn ọmọ Léfì láàárín wọn.+ 4 Ẹ̀yà méjì ni wọ́n ka àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù sí,+ ìyẹn Mánásè àti Éfúrémù;+ wọn ò pín lára ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Léfì, àfi àwọn ìlú+ tí wọ́n á máa gbé àti ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn wọn á ti máa jẹko, tí ohun ìní wọn sì máa wà.+ 5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá pín ilẹ̀ náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.

6 Àwọn ọkùnrin Júdà wá bá Jóṣúà ní Gílígálì,+ Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè, ọmọ Kénásì sì sọ fún un pé: “O mọ ohun tí Jèhófà sọ+ dáadáa, ohun tó sọ fún Mósè èèyàn Ọlọ́run tòótọ́+ nípa èmi àti ìwọ ní Kadeṣi-báníà.+ 7 Ẹni ogójì (40) ọdún ni mí nígbà tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà rán mi láti Kadeṣi-báníà lọ ṣe amí ilẹ̀ náà,+ bọ́rọ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́* ni mo sọ ọ́ nígbà tí mo dé.+ 8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin mi tí a jọ lọ mú kí ọkàn àwọn èèyàn wa domi,* mo fi gbogbo ọkàn mi tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run mi.*+ 9 Mósè búra ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Ilẹ̀ tí o fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ̀ máa di ogún ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ títí lọ, torí pé o ti fi gbogbo ọkàn rẹ tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run mi.’+ 10 Bí Jèhófà ṣe ṣèlérí,+ ó dá ẹ̀mí mi sí+ jálẹ̀ ọdún márùndínláàádọ́ta (45) yìí, látìgbà tí Jèhófà ti ṣe ìlérí yìí fún Mósè, nígbà tí Ísírẹ́lì rìn nínú aginjù;+ èmi náà rèé lónìí, lẹ́ni ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún (85). 11 Mo ṣì lágbára lónìí bíi ti ọjọ́ tí Mósè rán mi jáde. Agbára mi ò dín kù sí tìgbà yẹn, mo lè jagun, mo sì lè ṣe àwọn nǹkan míì. 12 Torí náà, fún mi ní agbègbè olókè yìí, tí Jèhófà ṣèlérí ní ọjọ́ yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o gbọ́ lọ́jọ́ yẹn pé àwọn Ánákímù+ wà níbẹ̀, wọ́n sì ní àwọn ìlú olódi tó tóbi,+ ó dájú pé* Jèhófà máa wà pẹ̀lú mi,+ màá sì lé wọn kúrò,* bí Jèhófà ṣe ṣèlérí.”+

13 Jóṣúà wá súre fún un, ó sì fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ní Hébúrónì pé kó jẹ́ ogún rẹ̀.+ 14 Ìdí nìyẹn tí Hébúrónì fi jẹ́ ogún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ọmọ Kénásì títí dòní, torí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 15 Kiriati-ábà+ ni Hébúrónì ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ (Ábà jẹ́ ẹni ńlá láàárín àwọn Ánákímù). Ogun sì dáwọ́ dúró ní ilẹ̀ náà.+

15 Ilẹ̀ tí wọ́n pín+ fún ẹ̀yà Júdà ní ìdílé-ìdílé lọ dé ààlà Édómù,+ aginjù Síínì, dé ìpẹ̀kun Négébù lápá gúúsù. 2 Ààlà wọn lápá gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti ìkángun Òkun Iyọ̀,*+ láti ibi tí omi ti ya wọ ilẹ̀, tó dojú kọ gúúsù. 3 Ó sì lọ sápá gúúsù dé ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ákírábímù,+ ó dé Síínì, ó gba gúúsù lọ sí Kadeṣi-báníà,+ ó dé Hésírónì, lọ dé Ádáárì, ó sì yí gba ọ̀nà Káríkà. 4 Ó tún lọ dé Ásímónì,+ títí dé Àfonífojì Íjíbítì,+ ààlà náà sì parí sí Òkun.* Èyí ni ààlà wọn lápá gúúsù.

5 Ààlà wọn lápá ìlà oòrùn jẹ́ Òkun Iyọ̀* títí dé ìpẹ̀kun Jọ́dánì, ààlà náà ní igun apá àríwá jẹ́ ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀, ní ìpẹ̀kun Jọ́dánì.+ 6 Ààlà náà lọ dé Bẹti-hógílà,+ ó sì kọjá lọ lápá àríwá Bẹti-árábà,+ ààlà náà sì dé ibi òkúta Bóhánì+ ọmọ Rúbẹ́nì. 7 Ààlà náà tún dé Débírì ní Àfonífojì* Ákórì,+ ó sì yí gba apá àríwá lọ sí Gílígálì,+ tó wà níwájú ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ádúmímù, ní gúúsù àfonífojì, ààlà náà dé ibi omi Ẹ́ń-ṣímẹ́ṣì,+ ó sì parí sí Ẹ́ń-rógélì.+ 8 Ààlà náà dé Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ ààlà náà dé orí òkè tó dojú kọ Àfonífojì Hínómù lápá ìwọ̀ oòrùn, èyí tó wà ní ìkángun Àfonífojì* Réfáímù lápá àríwá. 9 Wọ́n pààlà náà látorí òkè dé ibi ìsun omi Néfítóà,+ ó sì lọ dé àwọn ìlú Òkè Éfúrónì; wọ́n tún pààlà dé Báálà, ìyẹn Kiriati-jéárímù.+ 10 Ààlà náà yí láti Báálà gba apá ìwọ̀ oòrùn lọ sí Òkè Séírì, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Jéárímù ní àríwá, ìyẹn Kẹ́sálónì, ó lọ sí Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ ó sì dé Tímúnà.+ 11 Ààlà náà tún lọ dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Ẹ́kírónì+ lápá àríwá, wọ́n sì pààlà náà dé Ṣíkẹ́rónì, ó kọjá lọ sí Òkè Báálà, ó dé Jábínéélì, ààlà náà sì parí sí òkun.

12 Ààlà náà lápá ìwọ̀ oòrùn ni Òkun Ńlá*+ àti èbúté rẹ̀. Èyí ni ààlà àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà ní ìdílé-ìdílé yí ká.

13 Ó fún Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè, ní ìpín láàárín àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà, ìpín náà ni Kiriati-ábà, (Ábà ni bàbá Ánákì), ìyẹn Hébúrónì.+ 14 Kélẹ́bù lé àwọn ọmọ Ánákì+ mẹ́ta kúrò níbẹ̀, ìyẹn: Ṣéṣáì, Áhímánì àti Tálímáì,+ àwọn àtọmọdọ́mọ Ánákì. 15 Ó sì gòkè látibẹ̀ lọ bá àwọn tó ń gbé Débírì+ jà. (Kiriati-séférì ni Débírì ń jẹ́ tẹ́lẹ̀.) 16 Kélẹ́bù sọ pé: “Ẹni tó bá pa Kiriati-séférì run, tó sì gbà á, màá fún un ní Ákúsà ọmọ mi pé kó fi ṣe aya.” 17 Ótíníẹ́lì+ ọmọ Kénásì,+ arákùnrin Kélẹ́bù sì gbà á. Torí náà, ó fún un ní Ákúsà+ ọmọ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya. 18 Nígbà tí ọmọbìnrin náà ń lọ sílé, ó rọ ọmọkùnrin náà pé kó tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ bàbá òun. Ọmọbìnrin náà wá sọ̀ kalẹ̀ látorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀.* Kélẹ́bù sì bi í pé: “Kí lo fẹ́?”+ 19 Ó sọ pé: “Jọ̀ọ́, bù kún mi, o ti fún mi ní ilẹ̀ kan ní gúúsù;* tún fún mi ní Guloti-máímù.”* Torí náà, ó fún un ní Gúlótì Òkè àti Gúlótì Ìsàlẹ̀.

20 Èyí ni ogún ẹ̀yà Júdà ní ìdílé-ìdílé.

21 Àwọn ìlú tó wà ní ìkángun ẹ̀yà Júdà lápá ibi tí ààlà Édómù+ wà ní gúúsù nìyí: Kábúséélì, Édérì, Jágúrì, 22 Kínà, Dímónà, Ádádà, 23 Kédéṣì, Hásórì, Ítínánì, 24 Sífù, Télémù, Béálótì, 25 Hasori-hádátà àti Kerioti-hésírónì, ìyẹn Hásórì, 26 Ámámù, Ṣímà, Móládà,+ 27 Hasari-gádà, Hẹ́ṣímónì, Bẹti-pélétì,+ 28 Hasari-ṣúálì, Bíá-ṣébà,+ Bisiotáyà, 29 Báálà, Ímù, Ésémù, 30 Élítóládì, Kẹ́sílì, Hóómà,+ 31 Síkílágì,+ Mádímánà, Sánsánà, 32 Lẹ́báótì, Ṣílíhímù, Áyínì àti Rímónì,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

33 Ní Ṣẹ́fẹ́là,+ àwọn ìlú náà ni: Éṣítáólì, Sórà,+ Áṣínà, 34 Sánóà, Ẹ́ń-gánímù, Tápúà, Énámù, 35 Jámútì, Ádúlámù,+ Sókọ̀, Ásékà,+ 36 Ṣááráímù,+ Ádítáímù àti Gédérà pẹ̀lú Gédérótáímù,* gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́rìnlá (14), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

37 Sénánì, Hádáṣà, Migidali-gádì, 38 Díléánì, Mísípè, Jókítéélì, 39 Lákíṣì,+ Bósíkátì, Ẹ́gílónì, 40 Kábónì, Lámámù, Kítílíṣì, 41 Gédérótì, Bẹti-dágónì, Náámà àti Mákédà,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́rìndínlógún (16), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

42 Líbínà,+ Étérì, Áṣánì,+ 43 Ífítà, Áṣínà, Nésíbù, 44 Kéílà, Ákísíbù àti Máréṣà, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́sàn-án pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

45 Ẹ́kírónì, àwọn àrọko rẹ̀* àtàwọn ìgbèríko rẹ̀; 46 láti Ẹ́kírónì sí apá ìwọ̀ oòrùn, gbogbo ibi tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Áṣídódì pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

47 Áṣídódì,+ àwọn àrọko rẹ̀* àti àwọn ìgbèríko rẹ̀; Gásà,+ àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, dé Àfonífojì Íjíbítì àti Òkun Ńlá* pẹ̀lú ibi tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.+

48 Ní agbègbè olókè, Ṣámírù, Játírì,+ Sókọ̀, 49 Dánà, Kiriati-sánà, ìyẹn Débírì, 50 Ánábù, Éṣítémò,+ Ánímù, 51 Góṣénì,+ Hólónì àti Gílò,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mọ́kànlá (11), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

52 Árábù, Dúmà, Éṣánì, 53 Jánímù, Bẹti-tápúà, Áfékà, 54 Húmítà, Kiriati-ábà, ìyẹn Hébúrónì+ àti Síórì, gbógbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́sàn-án pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

55 Máónì,+ Kámẹ́lì, Sífù,+ Jútà, 56 Jésírẹ́lì, Jókídéámù, Sánóà, 57 Kénì, Gíbíà àti Tímúnà;+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́wàá pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

58 Hálíhúlù, Bẹti-súrì, Gédórì, 59 Máárátì, Bẹti-ánótì àti Élítékónì, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́fà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

60 Kiriati-báálì, ìyẹn Kiriati-jéárímù+ àti Rábà, ó jẹ́ ìlú méjì pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

61 Ní aginjù, Bẹti-árábà,+ Mídínì, Sékákà, 62 Níbúṣánì, Ìlú Iyọ̀ àti Ẹ́ń-gédì,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́fà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

63 Àmọ́ àwọn ọkùnrin Júdà kò lè lé àwọn ará Jébúsì+ tó ń gbé Jerúsálẹ́mù+ lọ,+ torí náà àwọn ará Jébúsì ṣì ń gbé pẹ̀lú àwọn èèyàn Júdà ní Jerúsálẹ́mù títí di òní yìí.

16 Ilẹ̀ tí wọ́n fi kèké pín*+ fún àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù+ bẹ̀rẹ̀ láti Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò dé ibi omi tó wà lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò, ó gba inú aginjù láti Jẹ́ríkò lọ sí agbègbè olókè Bẹ́tẹ́lì.+ 2 Ó lọ láti Bẹ́tẹ́lì tó jẹ́ ti Lúsì títí dé ààlà àwọn Áríkì ní Átárótì, 3 ó wá lọ sí ìsàlẹ̀ lápá ìwọ̀ oòrùn dé ààlà àwọn ọmọ Jáfílétì títí lọ dé ààlà Bẹti-hórónì+ Ìsàlẹ̀ àti Gésérì,+ ó sì parí sí òkun.

4 Àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù,+ Mánásè àti Éfúrémù, wá gba ilẹ̀ wọn.+ 5 Ààlà àwọn àtọmọdọ́mọ Éfúrémù ní ìdílé-ìdílé nìyí: Ààlà ogún wọn lápá ìlà oòrùn ni Ataroti-ádárì+ títí dé Bẹti-hórónì Òkè,+ 6 ó sì dé òkun. Míkímẹ́tátì+ wà ní àríwá, ààlà náà sì yí gba apá ìlà oòrùn lọ sí Taanati-ṣílò, ó sì gba ìlà oòrùn lọ sí Jánóà. 7 Láti Jánóà, ó gba ìsàlẹ̀ lọ sí Átárótì àti Náárà, ó sì dé Jẹ́ríkò,+ títí lọ dé Jọ́dánì. 8 Láti Tápúà,+ ààlà náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé Àfonífojì Kánà, ó sì parí sí òkun.+ Èyí ni ogún ẹ̀yà Éfúrémù ní ìdílé-ìdílé; 9 àwọn àtọmọdọ́mọ Éfúrémù tún ní àwọn ìlú tí wọ́n yà sọ́tọ̀ ní àárín ogún Mánásè,+ gbogbo ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

10 Àmọ́ wọn ò lé àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ní Gésérì+ kúrò, àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbé láàárín Éfúrémù títí di òní yìí,+ wọ́n sì ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́ àṣekára.+

17 Kèké+ wá mú ẹ̀yà Mánásè,+ torí òun ni àkọ́bí Jósẹ́fù.+ Torí pé ọkùnrin ogun ni Mákírù+ àkọ́bí Mánásè, tó sì jẹ́ bàbá Gílíádì, ó gba Gílíádì àti Báṣánì.+ 2 Kèké sì mú àwọn àtọmọdọ́mọ Mánásè yòókù ní ìdílé-ìdílé, ó mú àwọn ọmọ Abi-ésérì,+ àwọn ọmọ Hélékì, àwọn ọmọ Ásíríélì, àwọn ọmọ Ṣékémù, àwọn ọmọ Héfà àti àwọn ọmọ Ṣẹ́mídà. Àwọn ni àtọmọdọ́mọ Mánásè ọmọ Jósẹ́fù, àwọn ọkùnrin ní ìdílé-ìdílé.+ 3 Àmọ́ Sélóféhádì,+ ọmọ Héfà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírù, ọmọ Mánásè kò bímọ ọkùnrin, obìnrin nìkan ló bí, orúkọ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ sì nìyí: Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà. 4 Wọ́n wá lọ bá àlùfáà Élíásárì,+ Jóṣúà ọmọ Núnì àti àwọn ìjòyè, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà ló pàṣẹ fún Mósè pé kó fún wa ní ogún láàárín àwọn arákùnrin wa.”+ Torí náà, ó fún wọn ní ogún láàárín àwọn arákùnrin bàbá wọn, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ.+

5 Ilẹ̀ mẹ́wàá ló tún kan Mánásè yàtọ̀ sí ilẹ̀ Gílíádì àti Báṣánì, tó wà ní òdìkejì* Jọ́dánì,+ 6 torí pé àwọn ọmọbìnrin Mánásè náà gba ogún pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ilẹ̀ Gílíádì sì wá di ti àwọn àtọmọdọ́mọ Mánásè yòókù.

7 Ààlà Mánásè bẹ̀rẹ̀ láti Áṣérì dé Míkímẹ́tátì,+ tó dojú kọ Ṣékémù,+ ààlà náà sì lọ sí apá gúúsù,* dé ilẹ̀ àwọn tó ń gbé ní Ẹ́ń-Tápúà. 8 Ilẹ̀ Tápúà+ di ti Mánásè, àmọ́ àwọn àtọmọdọ́mọ Éfúrémù ló ni Tápúà tó wà ní ààlà Mánásè. 9 Ààlà náà gba ìsàlẹ̀ lọ sí Àfonífojì Kánà, lápá gúúsù dé àfonífojì náà. Àwọn ìlú Éfúrémù wà láàárín àwọn ìlú Mánásè,+ ààlà Mánásè sì wà ní àríwá àfonífojì náà, ó wá parí sí òkun.+ 10 Éfúrémù ló ni apá gúúsù, Mánásè ló ni apá àríwá, òkun sì ni ààlà rẹ̀,+ wọ́n* dé Áṣérì lápá àríwá, wọ́n sì dé Ísákà lápá ìlà oòrùn.

11 Ní ilẹ̀ Ísákà àti Áṣérì, wọ́n fún Mánásè ní Bẹti-ṣéánì àti àwọn àrọko rẹ̀,* Íbíléámù+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Ẹ́ń-dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Táánákì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn tó ń gbé Mẹ́gídò àti àwọn àrọko rẹ̀, mẹ́ta nínú àwọn ibi tó ga.

12 Àmọ́ àwọn àtọmọdọ́mọ Mánásè ò lè gba àwọn ìlú yìí; àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbé ilẹ̀ yìí.+ 13 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di alágbára, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fipá kó àwọn ọmọ Kénáánì ṣiṣẹ́ àṣekára,+ àmọ́ wọn ò lé wọn kúrò* pátápátá.+

14 Àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù sọ fún Jóṣúà pé: “Kí ló dé tí o fi kèké yan ilẹ̀ kan,+ tí o sì fún wa* ní ìpín kan ṣoṣo pé kó jẹ́ ogún wa? Èèyàn púpọ̀ ni wá, torí Jèhófà ti bù kún wa títí di báyìí.”+ 15 Jóṣúà fún wọn lésì pé: “Tó bá jẹ́ pé ẹ pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, ẹ lọ sínú igbó, kí ẹ sì ṣán ibì kan fún ara yín níbẹ̀, ní ilẹ̀ àwọn Pérísì+ àti àwọn Réfáímù,+ tó bá jẹ́ pé agbègbè olókè Éfúrémù+ ti kéré jù fún yín.” 16 Àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù wá sọ pé: “Agbègbè olókè náà ò lè gbà wá, gbogbo àwọn ọmọ Kénáánì tó sì ń gbé ní ilẹ̀ àfonífojì ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun+ tó ní dòjé irin,* ìyẹn àwọn tó wà ní Bẹti-ṣéánì+ àti àwọn àrọko rẹ̀* àti àwọn tó wà ní Àfonífojì Jésírẹ́lì.”+ 17 Jóṣúà wá sọ fún ilé Jósẹ́fù, ó sọ fún Éfúrémù àti Mánásè pé: “Èèyàn púpọ̀ ni yín, ẹ sì lágbára gan-an. Kì í ṣe ilẹ̀ kan péré la máa fi kèké pín fún yín,+ 18 àmọ́ agbègbè olókè náà tún máa di tiyín.+ Bó tiẹ̀ jẹ́ pé igbó ni, ẹ máa ṣán an, ibẹ̀ ló sì máa jẹ́ ìkángun ilẹ̀ yín. Torí ẹ máa lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò níbẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lágbára, wọ́n sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin.”*+

18 Nígbà náà, gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé jọ sí Ṣílò,+ wọ́n sì to àgọ́ ìpàdé síbẹ̀,+ torí wọ́n ti ṣẹ́gun ilẹ̀ náà.+ 2 Àmọ́ ó ṣì ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọn ò tíì pín ogún fún. 3 Jóṣúà wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìgbà wo lẹ máa tó lọ gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ti fún yín?+ 4 Ẹ fún mi ní ọkùnrin mẹ́ta látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan kí n lè rán wọn jáde; kí wọ́n lọ rìn káàkiri ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì ṣètò bí wọ́n á ṣe pín in gẹ́gẹ́ bí ogún wọn. Kí wọ́n wá pa dà sọ́dọ̀ mi. 5 Kí wọ́n pín in sí ọ̀nà méje láàárín ara wọn.+ Júdà ṣì máa wà ní ilẹ̀ rẹ̀ lápá gúúsù,+ ilé Jósẹ́fù pẹ̀lú ṣì máa wà ní ilẹ̀ wọn lápá àríwá.+ 6 Ohun tí ẹ máa ṣe ni pé kí ẹ pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje, kí ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níbí, màá sì ṣẹ́ kèké lé e+ níbí fún yín níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa. 7 Àmọ́ a ò ní fún àwọn ọmọ Léfì ní ìpín kankan láàárín yín,+ torí pé iṣẹ́ àlùfáà Jèhófà ni ogún wọn;+ Gádì, Rúbẹ́nì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ti gba ogún wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fún wọn.”

8 Àwọn ọkùnrin náà múra láti lọ, Jóṣúà sì pàṣẹ fún àwọn tó máa ṣètò bí wọ́n á ṣe pín ilẹ̀ náà pé: “Ẹ lọ rìn káàkiri ilẹ̀ náà, kí ẹ ṣètò bí ẹ ṣe máa pín in, kí ẹ wá pa dà sọ́dọ̀ mi, màá sì ṣẹ́ kèké lé e níbí fún yín níwájú Jèhófà ní Ṣílò.”+ 9 Ni àwọn ọkùnrin náà bá lọ, wọ́n rìn káàkiri ilẹ̀ náà, wọ́n fi àwọn ìlú ibẹ̀ pín in sí ọ̀nà méje, wọ́n sì kọ ọ́ sínú ìwé. Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jóṣúà níbi tí wọ́n pàgọ́ sí ní Ṣílò. 10 Jóṣúà wá ṣẹ́ kèké fún wọn ní Ṣílò níwájú Jèhófà.+ Ibẹ̀ ni Jóṣúà ti pín ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn.+

11 Kèké mú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé, ilẹ̀ tí wọ́n sì fi kèké pín fún wọn wà láàárín àwọn èèyàn Júdà+ àtàwọn èèyàn Jósẹ́fù.+ 12 Ní apá àríwá, ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ láti Jọ́dánì, ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jẹ́ríkò+ ní àríwá, ó dé orí òkè lápá ìwọ̀ oòrùn, ó sì lọ títí dé aginjù Bẹti-áfénì.+ 13 Ààlà náà tún lọ láti ibẹ̀ dé Lúsì, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tó wà lápá gúúsù Lúsì, ìyẹn Bẹ́tẹ́lì;+ ààlà náà dé Ataroti-ádárì+ lórí òkè tó wà ní gúúsù Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀.+ 14 Wọ́n pààlà náà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì yí gba gúúsù láti ibi òkè tó dojú kọ Bẹti-hórónì lápá gúúsù; ó parí sí Kiriati-báálì, ìyẹn Kiriati-jéárímù,+ ìlú Júdà. Èyí ni apá ìwọ̀ oòrùn.

15 Apá gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti ìkángun Kiriati-jéárímù, ààlà náà sì lọ sápá ìwọ̀ oòrùn; ó dé ibi ìsun omi Néfítóà.+ 16 Ààlà náà lọ dé ìkángun òkè tó dojú kọ Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ èyí tó wà ní Àfonífojì* Réfáímù+ lápá àríwá, ó sì lọ dé Àfonífojì Hínómù, dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, títí dé Ẹ́ń-rógélì.+ 17 Wọ́n pààlà náà lápá àríwá, ó sì lọ dé Ẹ́ń-ṣímẹ́ṣì títí dé Gélílótì, èyí tó wà níwájú ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ádúmímù,+ ó wá lọ dé ibi òkúta+ Bóhánì+ ọmọ Rúbẹ́nì. 18 Ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá àríwá níwájú Árábà, ó sì lọ dé Árábà. 19 Ààlà náà tún lọ dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá àríwá Bẹti-hógílà,+ ó sì parí sí ibi tí omi ti ya wọ ilẹ̀ lápá àríwá Òkun Iyọ̀,*+ ní ìpẹ̀kun Jọ́dánì lápá gúúsù. Èyí ni ààlà náà lápá gúúsù. 20 Jọ́dánì sì ni ààlà rẹ̀ lápá ìlà oòrùn. Èyí ni ogún àwọn àtọmọdọ́mọ Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ààlà rẹ̀ yí ká.

21 Àwọn ìlú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé nìyí: Jẹ́ríkò, Bẹti-hógílà, Emeki-késísì, 22 Bẹti-árábà,+ Sémáráímù, Bẹ́tẹ́lì,+ 23 Áfímù, Párà, Ọ́fírà, 24 Kefari-ámónì, Ófínì àti Gébà,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú méjìlá (12) pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

25 Gíbíónì,+ Rámà, Béérótì, 26 Mísípè, Kéfírà, Mósáhì, 27 Rékémù, Iripéélì, Tárálà, 28 Séélà,+ Ha-éléfì, Jẹ́búsì, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ Gíbíà+ àti Kíríátì, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́rìnlá (14), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

Èyí ni ogún àwọn àtọmọdọ́mọ Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé.

19 Kèké kejì+ wá mú Síméónì, ẹ̀yà Síméónì+ ní ìdílé-ìdílé. Ogún wọn sì wà láàárín ogún Júdà.+ 2 Ogún wọn ni Bíá-ṣébà,+ pẹ̀lú Ṣébà, Móládà,+ 3 Hasari-ṣúálì,+ Bálà, Ésémù,+ 4 Élítóládì,+ Bẹ́túlì, Hóómà, 5 Síkílágì,+ Bẹti-mákábótì, Hasari-súsà, 6 Bẹti-lébáótì+ àti Ṣárúhénì, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́tàlá (13), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn; 7 Áyínì, Rímónì, Étérì àti Áṣánì,+ ó jẹ́ ìlú mẹ́rin pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn; 8 àti gbogbo ìgbèríko tó yí àwọn ìlú yìí ká títí dé Baalati-bíà, ìyẹn Rámà tó wà ní gúúsù. Èyí ni ogún ẹ̀yà Síméónì ní ìdílé-ìdílé. 9 Inú ìpín Júdà ni wọ́n ti mú ogún àwọn àtọmọdọ́mọ Síméónì, torí pé ìpín Júdà ti pọ̀ jù fún wọn. Torí náà, àwọn àtọmọdọ́mọ Síméónì gba ohun ìní tiwọn láàárín ogún wọn.+

10 Lẹ́yìn náà, kèké kẹta+ mú àwọn àtọmọdọ́mọ Sébúlúnì+ ní ìdílé-ìdílé, ààlà ogún wọn sì lọ títí dé Sárídì. 11 Ààlà wọn lọ sápá òkè ní ìwọ̀ oòrùn sí Márálà, ó dé Dábéṣétì, ó sì lọ sí àfonífojì tó wà níwájú Jókínéámù. 12 Ó lọ láti Sárídì sápá ìlà oòrùn níbi tí oòrùn ti ń yọ dé ààlà Kisiloti-tábórì, ó dé Dábérátì,+ ó sì tún dé Jáfíà. 13 Ó lọ látibẹ̀ sápá ìlà oòrùn níbi tí oòrùn ti ń yọ dé Gati-héférì,+ ó dé Ẹti-kásínì, ó sì tún dé Rímónì, títí lọ dé Néà. 14 Ààlà náà yí i ká ní àríwá, ó dé Hánátónì, ó sì parí sí Àfonífojì Ifita-élì, 15 àti Kátátì, Náhálálì, Ṣímúrónì,+ Ídálà àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú méjìlá (12), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn. 16 Èyí ni ogún àwọn àtọmọdọ́mọ Sébúlúnì ní ìdílé-ìdílé.+ Èyí sì ni àwọn ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

17 Kèké kẹrin+ mú Ísákà,+ àwọn àtọmọdọ́mọ Ísákà ní ìdílé-ìdílé. 18 Ààlà wọn dé Jésírẹ́lì,+ Kẹ́súlótì, Ṣúnémù,+ 19 Háfáráímù, Ṣíónì, Ánáhárátì, 20 Rábítì, Kíṣíónì, Ébésì, 21 Rémétì, Ẹ́ń-gánímù,+ Ẹ́ń-hádà àti Bẹti-pásésì. 22 Ààlà náà sì dé Tábórì,+ Ṣáhásúmà àti Bẹti-ṣémẹ́ṣì, ààlà wọn wá parí sí Jọ́dánì, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́rìndínlógún (16) pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn. 23 Èyí ni ogún ẹ̀yà Ísákà ní ìdílé-ìdílé,+ àwọn ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

24 Lẹ́yìn náà, kèké karùn-ún+ mú ẹ̀yà Áṣérì+ ní ìdílé-ìdílé. 25 Ààlà wọn sì ni Hélíkátì,+ Hálì, Béténì, Ákíṣáfù, 26 Alamélékì, Ámádì àti Míṣálì. Ó dé apá ìwọ̀ oòrùn lọ sí Kámẹ́lì,+ ó tún dé Ṣihori-líbínátì, 27 ó wá pa dà sápá ìlà oòrùn lọ sí Bẹti-dágónì, ó dé Sébúlúnì àti Àfonífojì Ifita-élì lápá àríwá, ó dé Bẹti-émékì àti Néélì, ó sì dé Kábúlù ní apá òsì, 28 ó dé Ébúrónì, Réhóbù, Hámónì àti Kánà títí lọ dé Sídónì Ńlá.+ 29 Ààlà náà sì pa dà sí Rámà títí dé Tírè+ tó jẹ́ ìlú olódi. Ó wá pa dà sí Hósà, ó sì parí sí òkun, ní agbègbè Ákísíbù, 30 Úmà, Áfékì+ àti Réhóbù,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú méjìlélógún (22), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn. 31 Èyí ni ogún ẹ̀yà Áṣérì ní ìdílé-ìdílé.+ Èyí sì ni àwọn ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

32 Kèké kẹfà+ mú àwọn àtọmọdọ́mọ Náfútálì, àwọn àtọmọdọ́mọ Náfútálì ní ìdílé-ìdílé. 33 Ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ láti Héléfì, láti ibi igi ńlá ní Sáánánímù+ àti Adami-nékébù pẹ̀lú Jábínéélì títí dé Lákúmì; ó sì parí sí Jọ́dánì. 34 Ààlà náà wá pa dà sápá ìwọ̀ oòrùn lọ sí Asinoti-tábórì, ó lọ látibẹ̀ sí Húkókù, ó sì dé Sébúlúnì ní gúúsù, ó tún dé Áṣérì ní ìwọ̀ oòrùn àti Júdà ní Jọ́dánì lápá ìlà oòrùn. 35 Àwọn ìlú olódi náà ni Sídíímù, Sérì, Hémátì,+ Rákátì, Kínérétì, 36 Ádámà, Rámà, Hásórì,+ 37 Kédéṣì,+ Édíréì, Ẹ́ń-hásórì, 38 Yírónì, Migidali-élì, Hórémù, Bẹti-ánátì àti Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mọ́kàndínlógún (19), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn. 39 Èyí ni ogún ẹ̀yà Náfútálì ní ìdílé-ìdílé,+ àwọn ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

40 Kèké keje+ mú ẹ̀yà Dánì+ ní ìdílé-ìdílé. 41 Ààlà ogún wọn sì ni Sórà,+ Éṣítáólì, Iri-ṣéméṣì, 42 Ṣáálábínì,+ Áíjálónì,+ Ítílà, 43 Élónì, Tímúnà,+ Ẹ́kírónì,+ 44 Élétékè, Gíbétónì,+ Báálátì, 45 Jéhúdù, Bẹne-bérákì, Gati-rímónì,+ 46 Me-jákónì àti Rákónì, ààlà náà sì dojú kọ Jópà.+ 47 Àmọ́ ilẹ̀ Dánì ti kéré jù fún wọn.+ Torí náà, wọ́n lọ bá Léṣémù + jà, wọ́n gbà á, wọ́n sì fi idà ṣá wọn balẹ̀. Ó di tiwọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀, wọ́n wá yí orúkọ Léṣémù pa dà sí Dánì, ìyẹn Dánì tó jẹ́ orúkọ baba ńlá wọn.+ 48 Èyí ni ogún ẹ̀yà Dánì ní ìdílé-ìdílé. Èyí sì ni àwọn ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

49 Bí wọ́n ṣe pín àwọn ilẹ̀ tí wọ́n jogún náà tán nìyí gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlú tó wà níbẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá fún Jóṣúà ọmọ Núnì ní ogún láàárín wọn. 50 Bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ, wọ́n fún un ní ìlú tó béèrè, ìyẹn Timunati-sírà,+ ní agbègbè olókè Éfúrémù, ó kọ́ ìlú náà, ó sì ń gbé inú rẹ̀.

51 Èyí ni àwọn ogún tí àlùfáà Élíásárì, Jóṣúà ọmọ Núnì àtàwọn olórí agbo ilé bàbá nínú ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi kèké pín+ ní Ṣílò+ níwájú Jèhófà, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ Bí wọ́n ṣe pín àwọn ilẹ̀ náà tán nìyẹn.

20 Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ yan àwọn ìlú ààbò fún ara yín,+ èyí tí mo ní kí Mósè sọ fún yín nípa rẹ̀, 3 kí ẹni tí kò bá mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn tàbí tó ṣèèṣì pa èèyàn* lè sá lọ síbẹ̀. Àwọn ìlú náà á sì jẹ́ ìlú ààbò fún yín lọ́wọ́ ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.+ 4 Kí ẹni náà sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí,+ kó dúró sí ẹnubodè ìlú náà,+ kó sì ro ẹjọ́ rẹ̀ ní etí àwọn àgbààgbà ìlú náà. Kí wọ́n wá gbà á sínú ìlú náà, kí wọ́n fún un ní ibì kan, kó sì máa bá wọn gbé. 5 Tí ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ bá ń lé e, kí wọ́n má fi apààyàn náà lé e lọ́wọ́, torí ṣe ló ṣèèṣì* pa ẹnì kejì rẹ̀, kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀.+ 6 Kó máa gbé ìlú náà, títí dìgbà tí wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú àpéjọ,+ kó sì wà níbẹ̀ títí àlùfáà àgbà tí wọ́n yàn sípò nígbà yẹn fi máa kú.+ Lẹ́yìn náà, apààyàn náà lè pa dà sí ìlú tó ti sá kúrò, ó sì lè wọ ìlú rẹ̀ àti ilé rẹ̀.’”+

7 Torí náà, wọ́n ya Kédéṣì+ ní Gálílì sọ́tọ̀* ní agbègbè olókè Náfútálì, Ṣékémù+ ní agbègbè olókè Éfúrémù àti Kiriati-ábà,+ ìyẹn Hébúrónì, ní agbègbè olókè Júdà. 8 Ní agbègbè Jọ́dánì, lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò, wọ́n yan Bésérì+ ní aginjù tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú* látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Rámótì+ ní Gílíádì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Gádì àti Gólánì+ ní Báṣánì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Mánásè.+

9 Àwọn ìlú yìí ni wọ́n yàn fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn àjèjì tó ń gbé láàárín wọn, kí ẹnikẹ́ni tó bá ṣèèṣì pa èèyàn* lè sá lọ síbẹ̀,+ kí ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má bàa pa á kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú àpéjọ náà.+

21 Àwọn olórí agbo ilé bàbá àwọn ọmọ Léfì wá lọ bá àlùfáà Élíásárì+ àti Jóṣúà ọmọ Núnì pẹ̀lú àwọn olórí agbo ilé bàbá nínú ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, 2 wọ́n sì sọ fún wọn ní Ṣílò+ ní ilẹ̀ Kénáánì pé: “Jèhófà pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé kí wọ́n fún wa ní àwọn ìlú tí a máa gbé, pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko wọn fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa.”+ 3 Torí náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú yìí+ àtàwọn ibi ìjẹko wọn látinú ogún tiwọn.+

4 Kèké mú ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì,+ wọ́n sì fi kèké pín* ìlú mẹ́tàlá (13) fún àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ àlùfáà Áárónì, látinú ìpín ẹ̀yà Júdà,+ ẹ̀yà Síméónì+ àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.+

5 Wọ́n sì fún* àwọn ọmọ Kóhátì tó ṣẹ́ kù ní ìlú mẹ́wàá, látinú ìpín àwọn ìdílé ẹ̀yà Éfúrémù,+ ẹ̀yà Dánì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè.+

6 Wọ́n fún àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ ní ìlú mẹ́tàlá (13) látinú ìpín àwọn ìdílé ẹ̀yà Ísákà, ẹ̀yà Áṣérì, ẹ̀yà Náfútálì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní Báṣánì.+

7 Wọ́n fún àwọn ọmọ Mérárì+ ní ìlú méjìlá (12) ní ìdílé-ìdílé látinú ìpín ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ẹ̀yà Sébúlúnì.+

8 Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi kèké pín àwọn ìlú yìí àtàwọn ibi ìjẹko wọn fún àwọn ọmọ Léfì nìyẹn, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+

9 Torí náà, wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú tí a dárúkọ yìí látinú ìpín ẹ̀yà Júdà àti ẹ̀yà Síméónì,+ 10 wọ́n sì fún àwọn ọmọ Áárónì, tó wá látinú ìdílé Kóhátì ọmọ Léfì, torí àwọn ni kèké kọ́kọ́ mú. 11 Wọ́n fún wọn ní Kiriati-ábà+ (Ábà ni bàbá Ánákì), ìyẹn Hébúrónì,+ ní agbègbè olókè Júdà àti àwọn ibi ìjẹko tó yí i ká. 12 Àmọ́ Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ni wọ́n fún ní pápá tó wà ní ìlú náà pẹ̀lú ìgbèríko rẹ̀ pé kó jẹ́ ohun ìní rẹ̀.+

13 Wọ́n fún àwọn ọmọ àlùfáà Áárónì ní ìlú ààbò tí ẹni tó bá pààyàn máa sá lọ,+ ìyẹn Hébúrónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Líbínà+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 14 Játírì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Éṣítémóà+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 15 Hólónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Débírì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 16 Áyínì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Jútà+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Bẹti-ṣémẹ́ṣì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́sàn-án látinú ìpín ẹ̀yà méjì yìí.

17 Látinú ìpín ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì: Gíbíónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Gébà pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀,+ 18 Ánátótì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Álímónì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́rin.

19 Gbogbo ìlú tí wọ́n fún àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì, àwọn àlùfáà, jẹ́ ìlú mẹ́tàlá (13) pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko wọn.+

20 Wọ́n fi kèké pín àwọn ìlú fún àwọn ìdílé ọmọ Kóhátì yòókù nínú àwọn ọmọ Léfì látinú ìpín ẹ̀yà Éfúrémù. 21 Wọ́n fún wọn ní ìlú ààbò tí ẹni tó bá pààyàn máa sá lọ,+ ìyẹn Ṣékémù+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ ní agbègbè olókè Éfúrémù, Gésérì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 22 Kíbúsáímù pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Bẹti-hórónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́rin.

23 Látinú ìpín ẹ̀yà Dánì: Élítékè pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Gíbétónì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 24 Áíjálónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Gati-rímónì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́rin.

25 Látinú ìpín ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè: Táánákì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Gati-rímónì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú méjì.

26 Gbogbo ìlú pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko wọn tí àwọn ìdílé ọmọ Kóhátì tí ó ṣẹ́ kù gbà jẹ́ mẹ́wàá.

27 Látinú ìpín ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, wọ́n fún àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ tí wọ́n jẹ́ ìdílé ọmọ Léfì ní ìlú ààbò tí ẹni tó bá pààyàn máa sá lọ, ìyẹn Gólánì+ ní Báṣánì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Bééṣítérà pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú méjì.

28 Látinú ìpín ẹ̀yà Ísákà:+ Kíṣíónì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Dábérátì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 29 Jámútì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Ẹ́ń-gánímù pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́rin.

30 Látinú ìpín ẹ̀yà Áṣérì:+ Míṣálì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Ábídónì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 31 Hélíkátì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Réhóbù+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́rin.

32 Látinú ìpín ẹ̀yà Náfútálì: ìlú ààbò+ tí ẹni tó bá pààyàn máa sá lọ, ìyẹn Kédéṣì+ ní Gálílì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Hamoti-dórì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Kátánì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́ta.

33 Gbogbo ìlú àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ìlú mẹ́tàlá (13) pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko wọn.

34 Wọ́n fún ìdílé àwọn ọmọ Mérárì,+ àwọn ọmọ Léfì tó ṣẹ́ kù ní àwọn ìlú yìí látinú ìpín ẹ̀yà Sébúlúnì:+ Jókínéámù+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Kárítà pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 35 Dímúnà pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Náhálálì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́rin.

36 Látinú ìpín ẹ̀yà Rúbẹ́nì: Bésérì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Jáhásì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀,+ 37 Kédémótì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Mẹ́fáátì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́rin.

38 Látinú ìpín ẹ̀yà Gádì:+ ìlú ààbò tí ẹni tó bá pààyàn máa sá lọ, ìyẹn Rámótì ní Gílíádì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Máhánáímù+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, 39 Hẹ́ṣíbónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Jásérì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́rin.

40 Gbogbo ìlú tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Mérárì ní ìdílé-ìdílé, àwọn tó ṣẹ́ kù nínú ìdílé àwọn ọmọ Léfì jẹ́ ìlú méjìlá (12).

41 Gbogbo ìlú àwọn ọmọ Léfì láàárín ohun ìní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ìlú méjìdínláàádọ́ta (48) pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko wọn.+ 42 Gbogbo àwọn ìlú yìí ló ní àwọn ibi ìjẹko tó yí wọn ká lọ́kọ̀ọ̀kan, bó ṣe rí ní gbogbo àwọn ìlú yìí nìyẹn.

43 Jèhófà fún Ísírẹ́lì ní gbogbo ilẹ̀ tó búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá wọn,+ wọ́n gbà á, wọ́n sì ń gbé inú rẹ̀.+ 44 Bákan náà, Jèhófà fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo àyíká wọn, bó ṣe búra fún àwọn baba ńlá wọn,+ ìkankan nínú àwọn ọ̀tá wọn ò sì lè dojú kọ wọ́n.+ Jèhófà fi gbogbo ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́.+ 45 Kò sí ìlérí* tí kò ṣẹ nínú gbogbo ìlérí dáadáa tí Jèhófà ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ló ṣẹ pátá.+

22 Jóṣúà wá ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, 2 ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ti ṣe gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ fún yín,+ ẹ sì ti tẹ̀ lé gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín.+ 3 Ẹ ò pa àwọn arákùnrin yín tì ní gbogbo àsìkò yìí, títí dòní;+ ẹ sì ń ṣe àwọn ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ.+ 4 Jèhófà Ọlọ́run yín ti wá fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi, bó ṣe ṣèlérí fún wọn.+ Torí náà, ẹ lè pa dà sí àgọ́ yín ní ilẹ̀ tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fún yín pé kí ẹ jogún ní òdìkejì* Jọ́dánì.+ 5 Kí ẹ ṣáà rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé àṣẹ àti Òfin tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fún yín,+ kí ẹ máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+ kí ẹ rọ̀ mọ́ ọn,+ kí ẹ sì máa fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín+ sìn ín.”+

6 Jóṣúà wá súre fún wọn, ó ní kí wọ́n máa lọ, wọ́n sì lọ sí àgọ́ wọn. 7 Mósè ti fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ogún ní Báṣánì,+ Jóṣúà sì ti fún ààbọ̀ ẹ̀yà náà tó kù àti àwọn arákùnrin wọn ní ilẹ̀ ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì.+ Bákan náà, nígbà tí Jóṣúà ní kí wọ́n máa lọ sí àgọ́ wọn, ó súre fún wọn, 8 ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìní pa dà lọ sí àgọ́ yín, pẹ̀lú ẹran ọ̀sìn tó pọ̀, fàdákà àti wúrà, bàbà àti irin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ.+ Ẹ kó ìpín yín nínú ẹrù àwọn ọ̀tá yín,+ ẹ̀yin àtàwọn arákùnrin yín.”

9 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù, ní Ṣílò, ní ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì pa dà sí ilẹ̀ Gílíádì,+ ilẹ̀ tí wọ́n jogún tí wọ́n sì ń gbé bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+ 10 Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Jọ́dánì ní ilẹ̀ Kénáánì, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì, pẹpẹ náà tóbi, ó sì fani mọ́ra. 11 Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù gbọ́+ táwọn èèyàn sọ pé: “Ẹ wò ó! Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ti mọ pẹpẹ kan sí ààlà ilẹ̀ Kénáánì ní agbègbè Jọ́dánì, lápá ibi tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” 12 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ nípa rẹ̀, gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ ní Ṣílò+ láti lọ bá wọn jà.

13 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá rán Fíníhásì+ ọmọ àlùfáà Élíásárì sí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ilẹ̀ Gílíádì, 14 ìjòyè mẹ́wàá sì bá a lọ, ìjòyè kan látinú agbo ilé kọ̀ọ̀kan ní gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ olórí agbo ilé bàbá rẹ̀ láàárín àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún* Ísírẹ́lì.+ 15 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ilẹ̀ Gílíádì, wọ́n sọ fún wọn pé:

16 “Ohun tí gbogbo àpéjọ Jèhófà sọ nìyí: ‘Irú ìwà ọ̀dàlẹ̀ wo lẹ hù sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì yìí?+ Ẹ ti pa dà lẹ́yìn Jèhófà lónìí, torí pé ẹ mọ pẹpẹ kan fún ara yín, ẹ sì wá ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà.+ 17 Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá ní Péórì kò tíì tó wa ni? A ò tíì wẹ ara wa mọ́ nínú rẹ̀ títí dòní, láìka ti àjàkálẹ̀ àrùn tó jà láàárín àpéjọ Jèhófà.+ 18 Ẹ wá fẹ́ pa dà lẹ́yìn Jèhófà lónìí! Tí ẹ bá ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà lónìí, ó máa bínú sí gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì lọ́la.+ 19 Tó bá jẹ́ torí pé ilẹ̀ yín jẹ́ aláìmọ́ ni, ẹ sọdá sí ilẹ̀ Jèhófà+ níbi tí àgọ́ ìjọsìn Jèhófà wà,+ kí ẹ sì máa gbé láàárín wa, àmọ́ ẹ má ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ẹ má sì mọ pẹpẹ fún ara yín yàtọ̀ sí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run wa, kí ẹ sì fìyẹn sọ wá di ọlọ̀tẹ̀.+ 20 Nígbà tí Ákánì+ ọmọ Síírà hùwà àìṣòótọ́ lórí ọ̀rọ̀ ohun tí a máa pa run, ṣebí gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Ọlọ́run bínú sí?+ Òun nìkan kọ́ ló kú torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.’”+

21 Ni àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè bá dá àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún* Ísírẹ́lì+ lóhùn pé: 22 “Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọlọ́run!* Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọlọ́run!+ Ó mọ̀, Ísírẹ́lì náà sì máa mọ̀. Tí a bá ṣọ̀tẹ̀, tí a sì dalẹ̀ Jèhófà, má ṣe dá ẹ̀mí wa sí lónìí. 23 Tó bá jẹ́ torí ká lè pa dà lẹ́yìn Jèhófà la ṣe mọ pẹpẹ, ká sì lè máa rú àwọn ẹbọ sísun, ọrẹ ọkà àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ lórí rẹ̀, kí Jèhófà fìyà jẹ wá.+ 24 Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá, nǹkan míì la rò tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀, torí a sọ pé, ‘Lọ́jọ́ iwájú, àwọn ọmọ yín máa sọ fún àwọn ọmọ wa pé: “Kí ló pa ẹ̀yin àti Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì pọ̀? 25 Jèhófà ti fi Jọ́dánì ṣe ààlà láàárín àwa àti ẹ̀yin, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì. Ẹ ò ní ìpín kankan lọ́dọ̀ Jèhófà.” Àwọn ọmọ yín ò sì ní jẹ́ kí àwọn ọmọ wa jọ́sìn* Jèhófà.’

26 “Torí náà, a sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ ká rí i pé a ṣe nǹkan kan, ká mọ pẹpẹ kan, kì í ṣe fún ẹbọ sísun tàbí àwọn ẹbọ, 27 àmọ́ kó lè jẹ́ ẹ̀rí láàárín ẹ̀yin àti àwa+ pẹ̀lú àwọn àtọmọdọ́mọ* wa lẹ́yìn wa pé a máa fi àwọn ẹbọ sísun wa, àwọn ẹbọ wa àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ wa jọ́sìn Jèhófà níwájú rẹ̀, kí àwọn ọmọ yín má bàa sọ fún àwọn ọmọ wa lọ́jọ́ iwájú pé: “Ẹ ò ní ìpín kankan lọ́dọ̀ Jèhófà.”’ 28 A wá sọ pé, ‘Tí wọ́n bá sọ bẹ́ẹ̀ fún àwa àti àwọn àtọmọdọ́mọ wa lọ́jọ́ iwájú, a máa sọ pé: “Ẹ wo irú pẹpẹ Jèhófà tí àwọn baba ńlá wa mọ, kì í ṣe fún ẹbọ sísun tàbí fún àwọn ẹbọ, àmọ́ ó jẹ́ ẹ̀rí láàárín ẹ̀yin àti àwa.”’ 29 Kò ṣeé gbọ́ pé a ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ká sì pa dà lẹ́yìn Jèhófà+ lónìí torí pé a mọ pẹpẹ láti máa fi rú ẹbọ sísun, ọrẹ ọkà àti àwọn ẹbọ, yàtọ̀ sí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run wa tó wà níwájú àgọ́ ìjọsìn rẹ̀!”+

30 Nígbà tí Fíníhásì àlùfáà, àwọn ìjòyè àpéjọ náà àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún* Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ ohun tí àwọn àtọmọdọ́mọ Rúbẹ́nì, Gádì àti àwọn ọmọ Mánásè sọ, ó tẹ́ wọn lọ́rùn.+ 31 Ni Fíníhásì ọmọ àlùfáà Élíásárì bá sọ fún àwọn àtọmọdọ́mọ Rúbẹ́nì, Gádì àti àwọn ọmọ Mánásè pé: “Lónìí, a mọ̀ pé Jèhófà wà láàárín wa, torí ẹ ò hùwà ọ̀dàlẹ̀ yìí sí Jèhófà. Ẹ ti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ Jèhófà.”

32 Fíníhásì ọmọ àlùfáà Élíásárì àti àwọn ìjòyè wá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì ní ilẹ̀ Gílíádì lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì wá jábọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù. 33 Ìròyìn náà tẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́rùn. Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń yin Ọlọ́run, wọn ò sì sọ pé àwọn máa lọ bá àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì jà mọ́, kí wọ́n lè run ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé.

34 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì wá sọ pẹpẹ náà lórúkọ,* torí pé “ó jẹ́ ẹ̀rí láàárín wa pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.”

23 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí Jèhófà ti fún Ísírẹ́lì ní ìsinmi+ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá tó yí wọn ká, tí Jóṣúà ti darúgbó, tó sì ti lọ́jọ́ lórí,+ 2 Jóṣúà pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ,+ àwọn àgbààgbà wọn, àwọn olórí, àwọn onídàájọ́ àtàwọn aṣojú wọn,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Mo ti darúgbó; mo sì ti lọ́jọ́ lórí. 3 Ẹ̀yin fúnra yín ti rí gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí nítorí yín, torí pé Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń jà fún yín.+ 4 Ẹ wò ó, mo fi kèké+ pín* ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́ kù fún yín pé kó jẹ́ ogún àwọn ẹ̀yà yín,+ mo sì tún pín ilẹ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo pa run fún yín,+ láti Jọ́dánì dé Òkun Ńlá* ní ìwọ̀ oòrùn.* 5 Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń tì wọ́n kúrò níwájú yín, ó lé wọn kúrò* fún yín,+ ẹ sì gba ilẹ̀ wọn, bí Jèhófà Ọlọ́run yín ti ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́.+

6 “Torí náà, ẹ jẹ́ onígboyà gidigidi kí ẹ lè máa pa gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé Òfin+ Mósè mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé e, kí ẹ má ṣe yà kúrò nínú rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ 7 ẹ má ṣe bá àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́ kù pẹ̀lú yín yìí ṣe wọlé-wọ̀de.+ Ẹ ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ dárúkọ àwọn ọlọ́run wọn,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ fi wọ́n búra, ẹ ò gbọ́dọ̀ sìn wọ́n láé, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn.+ 8 Àmọ́ kí ẹ rọ̀ mọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín,+ bí ẹ ṣe ṣe títí dòní. 9 Jèhófà máa lé àwọn orílẹ̀-èdè tó tóbi tó sì lágbára kúrò níwájú yín,+ torí kò tíì sí ẹni tó lè dojú kọ yín títí dòní.+ 10 Ẹnì kan péré nínú yín máa lé ẹgbẹ̀rún (1,000),+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ń jà fún yín+ bó ṣe ṣèlérí fún yín.+ 11 Torí náà, ẹ máa ṣọ́ra ní gbogbo ìgbà,*+ kí ẹ máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín.+

12 “Àmọ́ tí ẹ bá yí pa dà pẹ́nrẹ́n, tí ẹ sì rọ̀ mọ́ ìyókù àwọn orílẹ̀-èdè yìí, tí wọ́n ṣẹ́ kù+ pẹ̀lú yín, tí ẹ bá wọn dána,*+ tí ẹ sì ń bára yín ṣọ̀rẹ́, 13 kí ẹ mọ̀ dájú pé Jèhófà Ọlọ́run yín kò ní bá yín lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò* mọ́.+ Wọ́n máa di pańpẹ́ àti ìdẹkùn fún yín, wọ́n máa di pàṣán ní ẹ̀gbẹ́ yín+ àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ fi máa pa run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fún yín.

14 “Ẹ wò ó! Mi ò ní pẹ́ kú,* ẹ sì mọ̀ dáadáa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín pé kò sí ìkankan nínú gbogbo ìlérí tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe fún yín tí kò ṣẹ. Gbogbo wọn ló ṣẹ fún yín. Ìkankan nínú wọn ò kùnà.+ 15 Àmọ́ bí gbogbo ìlérí tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe fún yín ṣe ṣẹ sí yín lára,+ bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà máa mú gbogbo àjálù tó ṣèlérí* wá sórí yín, ó sì máa pa yín run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fún yín.+ 16 Tí ẹ bá da májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín tó pa láṣẹ pé kí ẹ máa pa mọ́, tí ẹ bá sì lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ̀ ń forí balẹ̀ fún wọn, Jèhófà máa bínú sí yín gidigidi,+ ẹ sì máa pa run kíákíá lórí ilẹ̀ dáradára tó fún yín.”+

24 Jóṣúà wá kó gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì jọ sí Ṣékémù, ó pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì, àwọn olórí wọn, àwọn onídàájọ́ àti àwọn aṣojú,+ wọ́n sì dúró síwájú Ọlọ́run tòótọ́. 2 Jóṣúà sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Òdìkejì Odò* ni àwọn baba ńlá yín+ gbé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn,+ ìyẹn Térà bàbá Ábúráhámù àti bàbá Náhórì, àwọn ọlọ́run míì ni wọ́n sì jọ́sìn.+

3 “‘Nígbà tó yá, mo mú Ábúráhámù  + baba ńlá yín láti òdìkejì Odò,* mo mú kó rin gbogbo ilẹ̀ Kénáánì já, mo sì sọ àwọn ọmọ* rẹ̀ di púpọ̀.+ Mo fún un ní Ísákì;+ 4 mo sì fún Ísákì ní Jékọ́bù àti Ísọ̀.+ Lẹ́yìn náà, mo fún Ísọ̀ ní Òkè Séírì pé kó di tirẹ̀;+ Jékọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì lọ sí Íjíbítì.+ 5 Nígbà tó yá, mo rán Mósè àti Áárónì,+ mo sì fi ohun tí mo ṣe láàárín wọn mú ìyọnu bá Íjíbítì,+ mo sì mú yín jáde. 6 Nígbà tí mo mú àwọn bàbá yín kúrò ní Íjíbítì,+ tí ẹ sì dé òkun, àwọn ará Íjíbítì ń fi àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn agẹṣin lé àwọn bàbá yín títí dé Òkun Pupa.+ 7 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà,+ ó wá fi òkùnkùn sáàárín ẹ̀yin àti àwọn ará Íjíbítì, ó mú kí òkun ya wá sórí wọn, ó bò wọ́n mọ́lẹ̀,+ ẹ sì fi ojú ara yín rí ohun tí mo ṣe ní Íjíbítì.+ Ọ̀pọ̀ ọdún* lẹ fi wà ní aginjù.+

8 “‘Mo mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn Ámórì tí wọ́n ń gbé ní òdìkejì* Jọ́dánì, wọ́n sì bá yín jà.+ Àmọ́ mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, kí ẹ lè gba ilẹ̀ wọn, mo sì pa wọ́n run kúrò níwájú yín.+ 9 Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù sì dìde, ó bá Ísírẹ́lì jà. Torí náà, ó ránṣẹ́ pe Báláámù ọmọ Béórì pé kó wá gégùn-ún fún yín.+ 10 Àmọ́ mi ò fetí sí Báláámù.+ Torí náà, ó súre fún yín léraléra,+ mo sì gbà yín lọ́wọ́ rẹ̀.+

11 “‘Lẹ́yìn náà, ẹ sọdá Jọ́dánì,+ ẹ sì dé Jẹ́ríkò.+ Àwọn olórí* ìlú Jẹ́ríkò, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Gẹ́gáṣì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì bá yín jà, àmọ́ mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.+ 12 Torí náà, mo mú kí àwọn èèyàn rẹ̀wẹ̀sì* kí ẹ tó dé ọ̀dọ̀ wọn, ìyẹn sì mú kí wọ́n sá kúrò níwájú yín,+ ìyẹn ọba Ámórì méjèèjì. Kì í ṣe idà yín tàbí ọfà yín ló ṣe èyí.+ 13 Mo wá fún yín ní ilẹ̀ tí ẹ ò ṣiṣẹ́ fún àti àwọn ìlú tí ẹ ò kọ́,+ ẹ sì ń gbé inú wọn. Ẹ tún ń jẹ àwọn èso ọgbà àjàrà àti àwọn èso igi ólífì tí ẹ ò gbìn.’+

14 “Torí náà, ẹ bẹ̀rù Jèhófà, kí ẹ sì máa fi ìwà títọ́* àti òótọ́ inú* sìn ín,+ kí ẹ mú àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín sìn ní òdìkejì Odò* àti ní Íjíbítì kúrò,+ kí ẹ sì máa sin Jèhófà. 15 Àmọ́ tó bá dà bíi pé ó burú lójú yín láti máa sin Jèhófà, ẹ fúnra yín yan ẹni tí ẹ fẹ́ máa sìn lónìí,+ bóyá àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín sìn ní òdìkejì Odò*+ tàbí àwọn ọlọ́run àwọn Ámórì tí ẹ̀ ń gbé ní ilẹ̀ wọn.+ Ṣùgbọ́n ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”

16 Àwọn èèyàn náà dáhùn pé: “Kò ṣeé gbọ́ pé a fi Jèhófà sílẹ̀, a wá lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì. 17 Jèhófà Ọlọ́run wa ló mú àwa àti àwọn bàbá wa kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kúrò ní ilé ẹrú,+ òun ló ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó kàmàmà yìí níṣojú wa,+ tó sì ń ṣọ́ wa ní gbogbo ọ̀nà tí a rìn àti lọ́dọ̀ gbogbo àwọn èèyàn tí a gba àárín wọn kọjá.+ 18 Jèhófà lé gbogbo àwọn èèyàn náà kúrò, títí kan àwọn Ámórì, tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà ṣáájú wa. Torí náà, Jèhófà ni àwa náà máa sìn, torí òun ni Ọlọ́run wa.”

19 Jóṣúà wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ ò lè sin Jèhófà, torí pé Ọlọ́run mímọ́ ni;+ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo ni.+ Kò ní dárí àwọn ìṣìnà* àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.+ 20 Tí ẹ bá fi Jèhófà sílẹ̀, tí ẹ sì ń sin àwọn ọlọ́run àjèjì, òun náà máa kẹ̀yìn sí yín, ó sì máa pa yín run lẹ́yìn tó ti ṣe ohun rere fún yín.”+

21 Àmọ́ àwọn èèyàn náà sọ fún Jóṣúà pé: “Rárá o, Jèhófà la máa sìn!”+ 22 Torí náà, Jóṣúà sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lòdì sí ara yín pé, ẹ̀yin fúnra yín lẹ pinnu pé Jèhófà lẹ máa sìn.”+ Wọ́n fèsì pé: “Àwa ni ẹlẹ́rìí.”

23 “Torí náà, ẹ mú àwọn ọlọ́run àjèjì tó wà láàárín yín kúrò, kí ẹ sì yí ọkàn yín sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” 24 Àwọn èèyàn náà sọ fún Jóṣúà pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa la máa sìn, ohùn rẹ̀ la ó sì máa fetí sí!”

25 Jóṣúà wá bá àwọn èèyàn náà dá májẹ̀mú ní ọjọ́ yẹn, ó sì fi ìlànà àti òfin lélẹ̀ fún wọn ní Ṣékémù. 26 Jóṣúà wá kọ ọ̀rọ̀ yìí sínú ìwé Òfin Ọlọ́run,+ ó gbé òkúta ńlá kan,+ ó sì gbé e kalẹ̀ sábẹ́ igi ńlá tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi mímọ́ Jèhófà.

27 Jóṣúà sì sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ wò ó! Òkúta yìí máa jẹ́ ẹ̀rí lòdì sí wa,+ torí ó ti gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà bá wa sọ, ó sì máa jẹ́ ẹ̀rí lòdì sí yín, kí ẹ má bàa sẹ́ Ọlọ́run yín.” 28 Ni Jóṣúà bá ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, kí kálukú pa dà síbi ogún rẹ̀.+

29 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jóṣúà ọmọ Núnì, ìránṣẹ́ Jèhófà, kú lẹ́ni àádọ́fà (110) ọdún.+ 30 Wọ́n sin ín sí ilẹ̀ tó jogún ní Timunati-sírà,+ èyí tó wà ní agbègbè olókè Éfúrémù, ní àríwá Òkè Gááṣì. 31 Ísírẹ́lì ṣì ń sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ ayé àwọn àgbààgbà tí wọ́n ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí Jóṣúà kú, tí wọ́n sì ti mọ gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe nítorí Ísírẹ́lì.+

32 Wọ́n sin àwọn egungun Jósẹ́fù,+ èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó kúrò ní Íjíbítì sí Ṣékémù lórí ilẹ̀ tí Jékọ́bù fi ọgọ́rùn-ún (100) ẹyọ owó+ rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì,+ bàbá Ṣékémù; ó sì di ogún àwọn ọmọ Jósẹ́fù.+

33 Bákan náà, Élíásárì ọmọ Áárónì kú.+ Wọ́n sì sin ín sí Òkè Fíníhásì ọmọ rẹ̀,+ èyí tí wọ́n fún un ní agbègbè olókè Éfúrémù.

Tàbí “Jèhóṣúà,” ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.”

Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.

Tàbí “lápá ibi tí oòrùn ti ń wọ̀.”

Tàbí “ṣàṣàrò lórí rẹ̀.”

Ìyẹn, ní apá ìlà oòrùn.

Ìyẹn, ní apá ìlà oòrùn.

Tàbí “ìpayà bá wa.”

Ní Héb., “ẹ̀mí ò sì dìde nínú ẹnikẹ́ni.”

Tàbí “tó ṣeé gbà gbọ́.”

Tàbí “ọkàn wa.”

Tàbí “Ọkàn wa máa kú dípò tiyín.”

Tàbí “wíńdò.”

Tàbí “tí ọwọ́ bá tẹ.”

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”

Nǹkan bíi mítà 890 (ẹsẹ̀ bàtà 2,920). Wo Àfikún B14.

Ní Héb., “kanlẹ̀ nínú.”

Tàbí “ògiri.”

Tàbí “ògiri.”

Ìyẹn, Òkun Òkú.

Ní Héb., “ọmọkùnrin.”

Ní Héb., “bẹ̀rù rẹ̀.”

Ní Héb., “lápá ibi tí òkun wà ní.”

Tàbí “ìpayà bá wọn.”

Ní Héb., “kò sì sí ẹ̀mí kankan mọ́ nínú wọn.”

Tàbí “kọlà fún.”

Ó túmọ̀ sí “Òkè Adọ̀dọ́.”

Tàbí “àwọn ọkùnrin tó dàgbà tó láti jagun.”

Ó túmọ̀ sí “Yí; Yí Kúrò.”

Tàbí “balógun.”

Tàbí “ìró ìwo tó ń dún lala.”

Tàbí “wàhálà; ìtanùlẹ́gbẹ́.”

Tàbí kó jẹ́, “mú kí àwọn èèyàn náà búra.”

Ó túmọ̀ sí “Ibi Tí Wọ́n Ti Ń Wa Òkúta.”

Tàbí “ìgboyà.”

Ìyẹn, apá ìlà oòrùn.

Tàbí “yí pa dà lẹ́yìn.”

Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “wàhálà; ìtanùlẹ́gbẹ́.”

Ó túmọ̀ sí “Àjálù; Ìtanùlẹ́gbẹ́.”

Tàbí “tó sì pe àwọn ọmọ ogun jọ.”

Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “ẹ̀ṣín.”

Tàbí “igi.”

Ní Héb., “tó ń rìn.”

Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.

Tàbí “Ẹrú.”

Ìyẹn, apá ìlà oòrùn.

Tàbí “yẹ àwọn oúnjẹ wọn wò.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “Ọwọ́ rẹ la wà báyìí.”

Ní Héb., “Má dẹ ọwọ́ rẹ lọ́dọ̀ àwa ẹrú rẹ.”

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Ní Héb., “pọ́n ahọ́n rẹ̀.”

Tàbí “igi.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Árábà.”

Tàbí “já pátì.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “òkè kéékèèké rẹ̀.”

Ìyẹn, adágún odò Jẹ́nẹ́sárẹ́tì tàbí Òkun Gálílì.

Ìyẹn, Òkun Òkú.

Tàbí “ṣẹ́gun.”

Tàbí “láti Ṣíhórì.”

Ní Héb., “níwájú.”

Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”

Tàbí “mú wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn.”

Tàbí “òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”

Tàbí “mú wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn.”

Tàbí “kúrò lórí ilẹ̀ wọn.”

Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Ìyẹn, adágún odò Jẹ́nẹ́sárẹ́tì tàbí Òkun Gálílì.

Ìyẹn, apá ìlà oòrùn.

Ní Héb., “gẹ́lẹ́ lọ́kàn mi.”

Tàbí “kó ìpayà bá àwọn èèyàn wa.”

Ní Héb., “tọ Jèhófà Ọlọ́run mi lẹ́yìn délẹ̀délẹ̀.”

Tàbí “bóyá.”

Tàbí “mú wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn.”

Ìyẹn, Òkun Òkú.

Ìyẹn, Òkun Ńlá, Òkun Mẹditaréníà.

Ìyẹn, Òkun Òkú.

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.

Tàbí kó jẹ́, “ó pàtẹ́wọ́ látorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀.”

Tàbí “Négébù.”

Ó túmọ̀ sí “Bàsíà (Abọ́) Omi.”

Tàbí kó jẹ́, “Gédérà àtàwọn ọgbà àgùntàn rẹ̀.”

Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.

Tàbí “tí wọ́n pín.”

Ìyẹn, apá ìlà oòrùn.

Ní Héb., “apá ọ̀tún.”

Ìyẹn, àwọn ọmọ Mánásè tàbí ilẹ̀ Mánásè.

Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Tàbí “kúrò lórí ilẹ̀ wọn.”

Ní Héb., “mi.”

Ní Héb., “kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe.”

Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Ní Héb., “kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe.”

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Ìyẹn, Òkun Òkú.

Tàbí “pa ọkàn.”

Tàbí “kò mọ̀ọ́mọ̀.”

Ní Héb., “wọ́n ka Kédéṣì ní Gálílì sí mímọ́.”

Tàbí “òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”

Tàbí “pa ọkàn.”

Tàbí “wọ́n sì pín.”

Tàbí “Wọ́n sì fi kèké pín ilẹ̀ fún.”

Tàbí “ọ̀rọ̀.”

Ìyẹn, apá ìlà oòrùn.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Tàbí “agbo ilé.”

Tàbí “agbo ilé.”

Tàbí “Jèhófà, Ọlọ́run, Olú Ọ̀run.”

Ní Héb., “bẹ̀rù.”

Ní Héb., “àwọn ìran.”

Tàbí “agbo ilé.”

Pẹ̀lú àlàyé tí wọ́n ṣe yìí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ẹ̀rí ni wọ́n pe pẹpẹ náà.

Tàbí “mo pín.”

Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.

Tàbí “lápá ibi tí oòrùn ti ń wọ̀.”

Tàbí “ó mú wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn.”

Tàbí “Torí náà, ẹ máa ṣọ́ ọkàn yín lójú méjèèjì.”

Tàbí “tí ẹ̀ ń fẹ́ ara yín.”

Tàbí “mú àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò lórí ilẹ̀ wọn.”

Ní Héb., “Mò ń lọ ní ọ̀nà gbogbo ayé lónìí.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Tàbí “gbogbo ọ̀rọ̀ ibi náà.”

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “ọjọ́.”

Ìyẹn, apá ìlà oòrùn.

Tàbí kó jẹ́, “Àwọn onílẹ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “bẹ̀rù; wárìrì.”

Tàbí “sìn ín láìlẹ́bi.”

Tàbí “ìṣòtítọ́.”

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Tàbí “ọ̀tẹ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́