SÁMÚẸ́LÌ KEJÌ
1 Lẹ́yìn ikú Sọ́ọ̀lù, nígbà tí Dáfídì dé láti ibi tí ó ti lọ ṣẹ́gun* àwọn ọmọ Ámálékì, Dáfídì dúró sí Síkílágì+ fún ọjọ́ méjì. 2 Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan wá láti ibùdó Sọ́ọ̀lù, aṣọ rẹ̀ ti ya, iyẹ̀pẹ̀ sì wà lórí rẹ̀. Nígbà tí ó wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ó wólẹ̀, ó sì dọ̀bálẹ̀.
3 Dáfídì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ibo lo ti ń bọ̀?” Ó dáhùn pé: “Ibùdó Ísírẹ́lì ni mo ti sá wá.” 4 Dáfídì sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Báwo ni ọ̀hún ṣe rí? Jọ̀ọ́, sọ fún mi.” Ó dáhùn pé: “Àwọn èèyàn ti sá kúrò lójú ogun, ọ̀pọ̀ ló ti ṣubú tí wọ́n sì ti kú. Kódà Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ ti kú.”+ 5 Dáfídì bá béèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin tí ó wá ròyìn fún un pé: “Báwo lo ṣe mọ̀ pé Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ ti kú?” 6 Ọ̀dọ́kùnrin náà fèsì pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé mo wà ní orí Òkè Gíbóà,+ ni mo bá rí Sọ́ọ̀lù tó fi ara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀, àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn agẹṣin sì ti ká a mọ́.+ 7 Nígbà tí ó bojú wẹ̀yìn, tí ó rí mi, ó pè mí, mo sì sọ pé, ‘Èmi nìyí!’ 8 Ó béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Ta ni ọ́?’ Mo dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ Ámálékì+ ni mí.’ 9 Ni ó bá sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, kí o sì pa mí, nítorí mò ń jẹ̀rora gan-an, àmọ́ mo ṣì wà láàyè.’* 10 Torí náà, mo dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, mo sì pa á,+ nítorí mo mọ̀ pé kò lè yè é lẹ́yìn tí ó ti fara gbọgbẹ́ tí ó sì ti ṣubú. Lẹ́yìn náà, mo ṣí adé* orí rẹ̀, mo sì bọ́ ẹ̀gbà tó wà ní apá rẹ̀, mo sì kó wọn wá fún olúwa mi.”
11 Ni Dáfídì bá di ẹ̀wù ara rẹ̀ mú, ó sì fà á ya, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. 12 Wọ́n pohùn réré ẹkún, wọ́n sunkún, wọ́n sì gbààwẹ̀+ títí di ìrọ̀lẹ́ nítorí Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ àti nítorí àwọn èèyàn Jèhófà àti ilé Ísírẹ́lì+ torí pé wọ́n ti fi idà pa wọ́n.
13 Dáfídì béèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin tó wá ròyìn fún un pé: “Ibo lo ti wá?” Ó sọ pé: “Ọmọ Ámálékì ni bàbá mi, àjèjì ni nílẹ̀ Ísírẹ́lì.” 14 Ìgbà náà ni Dáfídì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ò fi bà ọ́ láti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti pa ẹni àmì òróró Jèhófà?”+ 15 Dáfídì bá pe ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀, ó sì sọ pé: “Bọ́ síwájú, kí o sì ṣá a balẹ̀.” Torí náà, ó ṣá a balẹ̀, ó sì kú.+ 16 Dáfídì sọ fún un pé: “Ẹ̀jẹ̀ rẹ wà ní orí ìwọ fúnra rẹ, nítorí ẹnu rẹ ló kó bá ọ, bí o ṣe sọ pé, ‘Èmi ni mo pa ẹni àmì òróró Jèhófà.’”+
17 Dáfídì wá kọ orin arò* yìí nítorí Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀,+ 18 ó sì ní kí wọ́n kọ́ àwọn èèyàn Júdà ní orin arò tí wọ́n pè ní “Ọrun,” tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Jáṣárì:+
19 “Ìwọ Ísírẹ́lì, wọ́n ti pa ẹwà lórí àwọn ibi gíga rẹ.+
Wo bí àwọn alágbára ṣe ṣubú!
20 Ẹ má sọ ọ́ ní Gátì;+
Ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní àwọn ojú ọ̀nà Áṣíkẹ́lónì,
Kí àwọn ọmọbìnrin Filísínì má bàa yọ̀,
Kí àwọn ọmọbìnrin àwọn aláìdádọ̀dọ́* má bàa dunnú.
21 Ẹ̀yin òkè Gíbóà,+
Kí ìrì má sẹ̀, kí òjò má sì rọ̀ sórí yín,
Bẹ́ẹ̀ ni kí pápá má ṣe mú ọrẹ mímọ́+ jáde,
Nítorí pé ibẹ̀ ni wọ́n ti sọ apata àwọn alágbára di aláìmọ́,
A kò sì fi òróró pa apata Sọ́ọ̀lù mọ́.
22 Ọrun Jónátánì+ àti idà Sọ́ọ̀lù+
Ti rẹ nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá, ó sì ti gún ọ̀rá àwọn jagunjagun,
Wọn kì í tàsé.
23 Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì,+ àwọn ẹni ọ̀wọ́n àti àyànfẹ́* nígbà ayé wọn,
A kò sì pín wọn níyà nígbà ikú wọn.+
24 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ísírẹ́lì, ẹ sunkún nítorí Sọ́ọ̀lù,
Ẹni tí ó fi aṣọ rírẹ̀dòdò àti ohun ọ̀ṣọ́ wọ̀ yín,
Ẹni tí ó fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára aṣọ yín.
25 Wo bí àwọn alágbára ṣe ṣubú lójú ogun!
Wọ́n ti pa Jónátánì sílẹ̀ lórí ibi gíga!+
Ìfẹ́ tí o ní sí mi lágbára ju ti obìnrin lọ.+
27 Wo bí àwọn alágbára ṣe ṣubú
Tí àwọn ohun ìjà sì ṣègbé!”
2 Lẹ́yìn náà, Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà+ pé: “Ṣé kí n lọ sínú ọ̀kan lára àwọn ìlú Júdà?” Jèhófà sọ fún un pé: “Lọ.” Dáfídì bá béèrè pé: “Ibo ni kí n lọ?” Ó fèsì pé: “Lọ sí Hébúrónì.”+ 2 Torí náà, Dáfídì lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìyàwó rẹ̀ méjèèjì, Áhínóámù+ ará Jésírẹ́lì àti Ábígẹ́lì+ opó Nábálì ará Kámẹ́lì. 3 Dáfídì tún mú àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀+ lọ, kálukú pẹ̀lú agbo ilé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní àwọn ìlú tó wà ní àyíká Hébúrónì. 4 Ìgbà náà ni àwọn ọkùnrin Júdà wá, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí ilé Júdà.+
Wọ́n sọ fún Dáfídì pé: “Àwọn ará Jabeṣi-gílíádì ló sin Sọ́ọ̀lù.” 5 Torí náà, Dáfídì rán àwọn òjíṣẹ́ sí àwọn ará Jabeṣi-gílíádì, ó sọ fún wọn pé: “Kí Jèhófà bù kún yín, nítorí ẹ fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Sọ́ọ̀lù, olúwa yín, ní ti pé ẹ sin ín.+ 6 Kí Jèhófà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìṣòtítọ́ hàn sí yín. Èmi náà máa ṣojú rere sí yín nítorí ohun tí ẹ ṣe yìí.+ 7 Ẹ má ṣe dẹwọ́, ẹ jẹ́ onígboyà, nítorí pé Sọ́ọ̀lù olúwa yín ti kú, ilé Júdà sì ti fòróró yàn mí ṣe ọba lórí wọn.”
8 Àmọ́ Ábínérì+ ọmọ Nérì, olórí ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù ti mú Íṣí-bóṣétì,+ ọmọ Sọ́ọ̀lù sọdá sí Máhánáímù,+ 9 ó sì fi jẹ ọba lórí Gílíádì+ àti àwọn Ááṣù, lórí Jésírẹ́lì + àti Éfúrémù,+ lórí Bẹ́ńjámínì àti gbogbo Ísírẹ́lì. 10 Ẹni ogójì (40) ọdún ni Íṣí-bóṣétì, ọmọ Sọ́ọ̀lù nígbà tó jọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì fi ọdún méjì ṣàkóso. Àmọ́ Dáfídì ni ilé Júdà ń tì lẹ́yìn.+ 11 Àkókò* tí Dáfídì fi jọba ní Hébúrónì lórí ilé Júdà jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.+
12 Nígbà tó yá, Ábínérì ọmọ Nérì àti àwọn ìránṣẹ́ Íṣí-bóṣétì, ọmọ Sọ́ọ̀lù kúrò ní Máhánáímù+ lọ sí Gíbíónì.+ 13 Jóábù+ ọmọ Seruáyà+ àti àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì náà jáde lọ, wọ́n sì pàdé wọn ní adágún odò tó wà ní Gíbíónì; àwùjọ kan jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kan adágún odò náà, nígbà tí àwùjọ kejì jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kejì adágún odò náà. 14 Níkẹyìn, Ábínérì sọ fún Jóábù pé: “Jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin dìde, kí wọ́n sì wọ̀yá ìjà* níwájú wa.” Jóábù bá sọ pé: “Kí wọ́n dìde.” 15 Nítorí náà, wọ́n dìde, àwùjọ méjèèjì sì yan iye àwọn tó máa sọdá, àwọn méjìlá (12) wá látọ̀dọ̀ Bẹ́ńjámínì àti Íṣí-bóṣétì, ọmọ Sọ́ọ̀lù, àwọn méjìlá (12) sì wá látọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. 16 Kálukú gbá orí ẹnì kejì rẹ̀ mú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ti idà rẹ̀ bọ ẹni tó dojú kọ ọ́ ní ẹ̀gbẹ́, gbogbo wọn sì ṣubú pa pọ̀. Torí náà, wọ́n pe ibẹ̀ ní Helikati-hásúrímù, èyí tó wà ní Gíbíónì.
17 Ìjà tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn le gan-an, níkẹyìn, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì ṣẹ́gun Ábínérì àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì. 18 Àwọn ọmọ Seruáyà+ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wà níbẹ̀, Jóábù,+ Ábíṣáì+ àti Ásáhélì;+ ẹsẹ̀ Ásáhélì sì yá nílẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín inú pápá. 19 Ásáhélì lé Ábínérì, kò sì yà sọ́tùn-ún tàbí kó yà sósì bó ṣe ń lépa Ábínérì. 20 Nígbà tí Ábínérì bojú wẹ̀yìn, ó ní: “Ásáhélì, ṣé ìwọ nìyẹn?” Ó dáhùn pé: “Èmi ni.” 21 Ábínérì wá sọ fún un pé: “Yà sí apá ọ̀tún tàbí sí apá òsì, kí o gbá ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin mú, kí o sì sọ ohun tí o bá bọ́ kúrò lára rẹ̀ di tìrẹ.” Àmọ́ Ásáhélì kò fẹ́ dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀. 22 Ábínérì bá sọ fún Ásáhélì lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi. Ṣé o fẹ́ kí n pa ọ́ ni? Kò yẹ kí n gbójú sókè wo Jóábù ẹ̀gbọ́n rẹ o.” 23 Àmọ́, ó kọ̀ kò dúró, torí náà Ábínérì fi ìdí ọ̀kọ̀ gún inú rẹ̀,+ ọ̀kọ̀ náà sì jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀; ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú lójú ẹsẹ̀. Gbogbo ẹni tó dé ibi tí Ásáhélì ṣubú sí, tí ó sì kú sí, ló dúró tó sì ń wò.
24 Lẹ́yìn náà, Jóábù àti Ábíṣáì lépa Ábínérì. Bí oòrùn ṣe ń wọ̀, wọ́n dé òkè Ámà tó dojú kọ Gíà lójú ọ̀nà tó lọ sí aginjù Gíbíónì. 25 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì kóra jọ sẹ́yìn Ábínérì, wọ́n di àwùjọ kan, wọ́n sì dúró sórí òkè kan. 26 Ábínérì wá nahùn pe Jóábù, ó ní: “Ṣé bí a ó ṣe máa fi idà pa ara wa lọ nìyí? Ṣé o ò mọ̀ pé ìkorò ló máa já sí ni? Ìgbà wo lo máa tó sọ fún àwọn èèyàn yìí pé kí wọ́n pa dà lẹ́yìn àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n ń lé?” 27 Ni Jóábù bá sọ pé: “Bí Ọlọ́run tòótọ́ ti wà láàyè, ká ní o ò sọ̀rọ̀ ni, àárọ̀ ọ̀la ni àwọn èèyàn náà ì bá tó pa dà lẹ́yìn àwọn arákùnrin wọn.” 28 Ni Jóábù bá fun ìwo, àwọn ọkùnrin rẹ̀ pa dà lẹ́yìn Ísírẹ́lì, ìjà náà sì dáwọ́ dúró.
29 Lẹ́yìn náà, Ábínérì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ gba Árábà+ kọjá ní gbogbo òru yẹn, wọ́n sọdá Jọ́dánì, wọ́n sì rin gbogbo ọ̀nà àfonífojì tóóró* jáde, níkẹyìn wọ́n dé Máhánáímù.+ 30 Lẹ́yìn ti Jóábù pa dà lẹ́yìn Ábínérì, ó kó gbogbo àwọn èèyàn náà jọ. Àwọn mọ́kàndínlógún (19) pẹ̀lú Ásáhélì ló dàwátì lára àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. 31 Àmọ́ àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì ti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì àti àwọn ọkùnrin Ábínérì, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgọ́ta (360) lára àwọn ọkùnrin wọn ló sì kú. 32 Wọ́n gbé Ásáhélì,+ wọ́n sì sin ín sí ibojì bàbá rẹ̀ tó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ Lẹ́yìn náà, Jóábù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ rìn láti òru mọ́jú, wọ́n sì dé Hébúrónì+ ní ìdájí.
3 Ogun tí ó wà láàárín ilé Sọ́ọ̀lù àti ilé Dáfídì kò tíì parí; bí Dáfídì ṣe túbọ̀ ń mókè+ ni ilé Sọ́ọ̀lù ń lọ sílẹ̀.+
2 Láàárín àkókò yìí, Dáfídì bí àwọn ọmọkùnrin ní Hébúrónì.+ Ámínónì+ ni àkọ́bí tí Áhínóámù+ ará Jésírẹ́lì bí fún un. 3 Ìkejì ni Kíléábù tí Ábígẹ́lì+ opó Nábálì ará Kámẹ́lì bí; ìkẹta ni Ábúsálómù+ ọmọ Máákà ọmọbìnrin Tálímáì+ ọba Géṣúrì. 4 Ìkẹrin ni Ádóníjà+ ọmọ Hágítì, ìkarùn-ún ni Ṣẹfatáyà ọmọ Ábítálì. 5 Ìkẹfà sì ni Ítíréámù tí Ẹ́gílà ìyàwó Dáfídì bí. Àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún Dáfídì nìyẹn ní Hébúrónì.
6 Bí ogun tó wà láàárín ilé Sọ́ọ̀lù àti ilé Dáfídì ṣe ń bá a lọ, agbára tí Ábínérì+ ní nílé Sọ́ọ̀lù ń pọ̀ sí i. 7 Sọ́ọ̀lù ní wáhàrì* kan tó ń jẹ́ Rísípà,+ ọmọ Áyà. Lẹ́yìn náà, Íṣí-bóṣétì + sọ fún Ábínérì pé: “Kí ló dé tí o fi bá wáhàrì bàbá mi lò pọ̀?”+ 8 Inú bí Ábínérì gan-an lórí ọ̀rọ̀ Íṣí-bóṣétì, ó sì sọ pé: “Ṣé ajá Júdà lo fi mí pè ni? Títí di òní yìí, mo ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ilé Sọ́ọ̀lù bàbá rẹ àti sí àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, mi ò sì gbẹ̀yìn lọ fi ọ́ lé Dáfídì lọ́wọ́; síbẹ̀ lónìí, o pè mí wá jíhìn ẹ̀ṣẹ̀ nítorí obìnrin. 9 Kí Ọlọ́run fìyà jẹ èmi Ábínérì gan-an, tí mi ò bá ṣe gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti búra fún Dáfídì+ pé: 10 Ìjọba náà máa kúrò ní ilé Sọ́ọ̀lù, a ó sì fìdí ìtẹ́ Dáfídì múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì àti lórí Júdà, láti Dánì dé Bíá-ṣébà.”+ 11 Íṣí-bóṣétì kò sì lè fèsì kankan nítorí ẹ̀rù Ábínérì bà á.+
12 Lójú ẹsẹ̀, Ábínérì rán àwọn òjíṣẹ́ sí Dáfídì pé: “Ta ló ni ilẹ̀ náà?” Ó tún sọ pé: “Bá mi dá májẹ̀mú, màá sì ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe* láti yí gbogbo Ísírẹ́lì sọ́dọ̀ rẹ.”+ 13 Ó fèsì pé: “Ó dáa! Màá bá ọ dá májẹ̀mú. Ohun kan ṣoṣo tí màá béèrè lọ́wọ́ rẹ ni pé, o ò gbọ́dọ̀ fojú kàn mí, àfi tí o bá mú Míkálì,+ ọmọ Sọ́ọ̀lù dání, nígbà tí o bá ń bọ̀ wá rí mi.” 14 Lẹ́yìn náà, Dáfídì rán àwọn òjíṣẹ́ sí Íṣí-bóṣétì,+ ọmọ Sọ́ọ̀lù, pé: “Fún mi ní Míkálì ìyàwó mi, ẹni tí mo fi ọgọ́rùn-ún (100) adọ̀dọ́ àwọn Filísínì+ fẹ́.” 15 Nítorí náà, Íṣí-bóṣétì ní kí wọ́n lọ mú un wá lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀, Pálítíélì+ ọmọ Láíṣì. 16 Ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ ń bá a rìn lọ, ó ń sunkún bí ó ṣe ń tẹ̀ lé e títí dé Báhúrímù.+ Ábínérì bá sọ fún un pé: “Ó yá, pa dà!” Nígbà náà, ó pa dà.
17 Láàárín àkókò yìí, Ábínérì ránṣẹ́ sí àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì pé: “Ó ti pẹ́ díẹ̀ tí ẹ ti fẹ́ kí Dáfídì jọba lórí yín. 18 Ní báyìí, ẹ gbé ìgbésẹ̀, nítorí Jèhófà ti sọ fún Dáfídì pé: ‘Nípasẹ̀ Dáfídì+ ìránṣẹ́ mi ni màá fi gba àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ àwọn Filísínì àti gbogbo àwọn ọ̀tá wọn.’” 19 Nígbà náà, Ábínérì bá àwọn èèyàn Bẹ́ńjámínì+ sọ̀rọ̀. Ábínérì sì tún lọ bá Dáfídì sọ̀rọ̀ ní Hébúrónì ní ìdákọ́ńkọ́ kí ó lè mọ ohun tí Ísírẹ́lì àti gbogbo ilé Bẹ́ńjámínì fohùn ṣọ̀kan láti ṣe.
20 Nígbà tí Ábínérì àti ogún (20) ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì, Dáfídì se àsè fún Ábínérì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. 21 Ni Ábínérì bá sọ fún Dáfídì pé: “Jẹ́ kí n lọ kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ olúwa mi ọba, kí wọ́n lè bá ọ dá májẹ̀mú, wàá sì di ọba lórí gbogbo àwọn tí o* fẹ́.” Nítorí náà, Dáfídì rán Ábínérì lọ, ó sì lọ ní àlàáfíà.
22 Kété lẹ́yìn náà, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì àti Jóábù dé láti ibi tí wọ́n ti lọ fi ogun kó ẹrù àwọn èèyàn, ohun tí wọ́n kó dé sì pọ̀ gan-an. Ábínérì kò sí lọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì mọ́, nítorí ó ti rán an lọ ní àlàáfíà. 23 Nígbà tí Jóábù+ àti gbogbo ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé, wọ́n ròyìn fún Jóábù pé: “Ábínérì+ ọmọ Nérì+ wá sọ́dọ̀ ọba, ó rán an lọ, ó sì lọ ní àlàáfíà.” 24 Nítorí náà, Jóábù wọlé lọ bá ọba, ó sì sọ pé: “Kí lo ṣe yìí? Ábínérì wá sọ́dọ̀ rẹ. Kí ló dé tí o fi rán an lọ, tí o sì jẹ́ kí ó lọ bẹ́ẹ̀? 25 Ṣebí o mọ Ábínérì ọmọ Nérì dáadáa! Torí kí ó lè tàn ọ́ ni ó ṣe wá, kí ó sì mọ gbogbo ìrìn rẹ àti gbogbo ohun tí ò ń ṣe.”
26 Jóábù bá jáde kúrò lọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì rán àwọn òjíṣẹ́ tẹ̀ lé Ábínérì, wọ́n mú un pa dà láti ibi kòtò omi Sáírà; ṣùgbọ́n Dáfídì kò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀. 27 Nígbà tí Ábínérì pa dà sí Hébúrónì,+ Jóábù mú un wọnú ibì kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè láti bá a sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́. Àmọ́, ibẹ̀ ni ó ti gún un ní ikùn, ó sì kú;+ èyí jẹ́ nítorí pé ó pa* Ásáhélì+ arákùnrin rẹ̀. 28 Nígbà tí Dáfídì wá gbọ́ nípa rẹ̀, ó ní: “Ọrùn èmi àti ìjọba mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀+ Ábínérì ọmọ Nérì níwájú Jèhófà títí láé. 29 Kí ó yí dà sórí Jóábù+ àti gbogbo ilé bàbá rẹ̀. Kí ọkùnrin tí nǹkan ń dà lára rẹ̀+ tàbí tí ó jẹ́ adẹ́tẹ̀ + tàbí tí ó yarọ* tàbí ẹni tí idà pa tàbí ẹni tí kò ní oúnjẹ+ má sì tán nílé Jóábù!” 30 Bí Jóábù àti Ábíṣáì+ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe pa Ábínérì+ nítorí pé ó pa Ásáhélì àbúrò wọn ní Gíbíónì lójú ogun+ nìyẹn.
31 Nígbà náà, Dáfídì sọ fún Jóábù àti gbogbo àwọn èèyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ẹ fa aṣọ yín ya, ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀,* kí ẹ sì pohùn réré ẹkún nítorí Ábínérì.” Ọba Dáfídì sì ń rìn bọ̀ lẹ́yìn àga ìgbókùú náà. 32 Wọ́n sin Ábínérì sí Hébúrónì; ọba sunkún kíkankíkan ní ibojì Ábínérì, gbogbo àwọn èèyàn náà sì sunkún. 33 Ọba sun rárà nítorí Ábínérì, ó sì sọ pé:
“Ṣé ó yẹ kí Ábínérì kú ikú òpònú?
34 Wọn ò de ọwọ́ rẹ,
Ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀* ò sì sí ní ẹsẹ̀ rẹ.
O ṣubú bí ẹni ṣubú níwájú ọ̀daràn.”*+
Gbogbo àwọn èèyàn náà bá tún bú sẹ́kún nítorí rẹ̀.
35 Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn náà wá fún Dáfídì ní oúnjẹ láti tù ú nínú* nígbà tí ilẹ̀ kò tíì ṣú, àmọ́ Dáfídì búra pé: “Kí Ọlọ́run fìyà jẹ mí gan-an, tí mo bá fi oúnjẹ tàbí ohunkóhun kan ẹnu+ kí oòrùn tó wọ̀!” 36 Gbogbo àwọn èèyàn náà fiyè sí i, ó sì dára lójú wọn. Bí gbogbo nǹkan tí ọba ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ ṣe dára lójú wọn, bẹ́ẹ̀ ni èyí náà dára lójú gbogbo àwọn èèyàn náà. 37 Gbogbo àwọn èèyàn náà àti gbogbo Ísírẹ́lì sì wá mọ̀ lọ́jọ́ yẹn pé ọba kọ́ ló ní kí wọ́n pa+ Ábínérì ọmọ Nérì. 38 Ìgbà náà ni ọba sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ò mọ̀ pé olórí àti èèyàn ńlá ni ẹni tó ṣubú lónìí yìí ní Ísírẹ́lì?+ 39 Ó rẹ̀ mí lónìí yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fòróró yàn mí ṣe ọba,+ ìwà àwọn ọkùnrin yìí, àwọn ọmọ Seruáyà,+ ti le jù fún mi.+ Kí Jèhófà san ibi pa dà fún ẹni tó ń hùwà ibi.”+
4 Nígbà tí Íṣí-bóṣétì+ ọmọ Sọ́ọ̀lù* gbọ́ pé Ábínérì ti kú ní Hébúrónì,+ ọkàn rẹ̀ domi,* ìdààmú sì bá gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 2 Àwọn ọkùnrin méjì kan wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn akónilẹ́rù* tó jẹ́ ti ọmọ Sọ́ọ̀lù: ọ̀kan ń jẹ́ Báánà, èkejì sì ń jẹ́ Rékábù. Ọmọ Rímónì ará Béérótì ni wọ́n, wọ́n wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. (Nítorí pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n máa ń ka Béérótì+ mọ́ ara Bẹ́ńjámínì. 3 Àwọn ará Béérótì sá lọ sí Gítáímù,+ wọ́n di àjèjì níbẹ̀, ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní yìí.)
4 Jónátánì,+ ọmọ Sọ́ọ̀lù, ní ọmọkùnrin kan tó rọ lẹ́sẹ̀.*+ Ọmọ ọdún márùn-ún ni nígbà tí wọ́n mú ìròyìn wá láti Jésírẹ́lì+ pé Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ti kú, ẹni tó ń tọ́jú rẹ̀ bá gbé e, ó sì sá lọ, àmọ́ bí ẹ̀rù ṣe ń ba obìnrin náà nígbà tó ń sá lọ, ọmọ náà já bọ́, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì rọ. Orúkọ rẹ̀ ni Méfíbóṣétì.+
5 Àwọn ọmọ Rímónì ará Béérótì, ìyẹn Rékábù àti Báánà, lọ sí ilé Íṣí-bóṣétì ní ọ̀sán gangan, nígbà tí ó ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́. 6 Wọ́n wọnú ilé náà bíi pé wọ́n fẹ́ wá kó àlìkámà,* wọ́n sì gún un ní ikùn; Rékábù àti Báánà+ arákùnrin rẹ̀ sì sá lọ. 7 Nígbà tí wọ́n wọnú ilé, ó ń sùn lórí ibùsùn nínú yàrá rẹ̀, wọ́n gún un pa, wọ́n sì gé orí rẹ̀ kúrò. Wọ́n gbé orí rẹ̀, wọ́n sì gba ọ̀nà tó lọ sí Árábà láti òru mọ́jú. 8 Wọ́n gbé orí Íṣí-bóṣétì + wá fún Dáfídì ní Hébúrónì, wọ́n sì sọ fún ọba pé: “Orí Íṣí-bóṣétì ọmọ Sọ́ọ̀lù ọ̀tá rẹ+ tí ó fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ+ rèé. Jèhófà ti bá olúwa mi ọba gbẹ̀san lára Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ lónìí yìí.”
9 Àmọ́, Dáfídì dá Rékábù àti Báánà arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rímónì ará Béérótì lóhùn pé: “Bí Jèhófà ẹni tí ó yọ mí* nínú gbogbo wàhálà+ ti wà láàyè, 10 nígbà tí ẹnì kan wá sọ fún mi pé, ‘Wò ó, Sọ́ọ̀lù ti kú,’+ ó rò pé ìròyìn ayọ̀ lòun mú wá fún mi, mo gbá a mú, mo sì pa á+ ní Síkílágì. Nǹkan tí mo fi san èrè iṣẹ́ tó wá jẹ́ nìyẹn! 11 Ṣé mi ò wá ní ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún àwọn èèyàn burúkú tó lọ pa ọkùnrin olódodo nínú ilé rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀? Ǹjẹ́ kò yẹ kí n béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yín,+ kí n sì mú yín kúrò lórí ilẹ̀?” 12 Dáfídì bá pàṣẹ pé kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin pa wọ́n.+ Wọ́n gé ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì gbé wọn kọ́+ sí ẹ̀gbẹ́ adágún odò ní Hébúrónì. Àmọ́ wọ́n gbé orí Íṣí-bóṣétì, wọ́n sì sín in sí ibi tí wọ́n sin Ábínérì sí ní Hébúrónì.
5 Nígbà tó yá, gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì,+ wọ́n sì sọ pé: “Wò ó! Ẹ̀jẹ̀* kan náà ni wá.+ 2 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí Sọ́ọ̀lù jẹ́ ọba wa, ìwọ lò ń kó Ísírẹ́lì jáde ogun.*+ Jèhófà sì sọ fún ọ pé: ‘Ìwọ ni wàá máa bójú tó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí àgùntàn, wàá sì di aṣáájú Ísírẹ́lì.’”+ 3 Nítorí náà, gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ ọba ní Hébúrónì, Ọba Dáfídì sì bá wọn dá májẹ̀mú+ ní Hébúrónì níwájú Jèhófà. Lẹ́yìn náà, wọ́n fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì.+
4 Ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún ni Dáfídì nígbà tí ó di ọba, ogójì (40) ọdún+ ló sì fi ṣàkóso. 5 Ọdún méje àti oṣù mẹ́fà ló fi jọba lórí Júdà ní Hébúrónì, ó sì fi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) ṣàkóso lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà ní Jerúsálẹ́mù.+ 6 Ọba àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ jáde lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ gbéjà ko àwọn ará Jébúsì+ tó ń gbé ilẹ̀ náà. Wọ́n pẹ̀gàn Dáfídì pé: “O ò ní wọ ibí yìí! Kódà àwọn afọ́jú àti àwọn arọ ló máa lé ọ dà nù.” Èrò wọn ni pé, ‘Dáfídì ò ní wọ ibí yìí.’+ 7 Síbẹ̀, Dáfídì gba ibi ààbò Síónì, èyí tó wá di Ìlú Dáfídì.+ 8 Nítorí náà, Dáfídì sọ lọ́jọ́ yẹn pé: “Kí àwọn tó máa lọ gbéjà ko àwọn ará Jébúsì gba ibi ihò omi wọlé láti pa ‘àwọn arọ àti àwọn afọ́jú,’ tí Dáfídì* kórìíra!” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sọ pé: “Àwọn afọ́jú àti àwọn arọ kò ní wọlé.” 9 Nígbà náà, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibi ààbò, wọ́n* sì pe ibẹ̀ ní Ìlú Dáfídì; Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́lé yí ká orí Òkìtì*+ àti láwọn ibòmíì nínú ìlú.+ 10 Bí agbára Dáfídì ṣe ń pọ̀ sí i+ nìyẹn, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+
11 Hírámù+ ọba Tírè rán àwọn òjíṣẹ́ sí Dáfídì, ó kó igi kédárì + ránṣẹ́, ó tún rán àwọn oníṣẹ́ igi àti àwọn oníṣẹ́ òkúta tó ń mọ ògiri sí Dáfídì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé* fún Dáfídì.+ 12 Dáfídì wá mọ̀ pé Jèhófà ti fìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì+ àti pé ó ti gbé ìjọba òun ga+ nítorí àwọn èèyàn Rẹ̀ Ísírẹ́lì.+
13 Dáfídì fẹ́ àwọn wáhàrì*+ àti àwọn ìyàwó míì ní Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tí ó dé láti Hébúrónì, wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin púpọ̀ sí i fún Dáfídì.+ 14 Orúkọ àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún un ní Jerúsálẹ́mù nìyí: Ṣámúà, Ṣóbábù, Nátánì,+ Sólómọ́nì,+ 15 Íbárì, Élíṣúà, Néfégì, Jáfíà, 16 Élíṣámà, Élíádà àti Élífélétì.
17 Nígbà tí àwọn Filísínì gbọ́ pé wọ́n ti fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì,+ gbogbo àwọn Filísínì bẹ̀rẹ̀ sí í wá Dáfídì.+ Bí Dáfídì ṣe gbọ́ báyìí, ó lọ sí ibi ààbò.+ 18 Ìgbà náà ni àwọn Filísínì wọlé wá, wọ́n sì dúró káàkiri ní Àfonífojì* Réfáímù.+ 19 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà+ pé: “Ṣé kí n lọ gbéjà ko àwọn Filísínì? Ṣé wàá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Ni Jèhófà bá sọ fún Dáfídì pé: “Lọ, torí ó dájú pé màá fi àwọn Filísínì lé ọ lọ́wọ́.”+ 20 Torí náà, Dáfídì wá sí Baali-pérásímù, Dáfídì sì pa wọ́n níbẹ̀. Ni ó bá sọ pé: “Jèhófà ti ya lu àwọn ọ̀tá mi+ níwájú mi, bí ìgbà tí omi bá ya lu nǹkan.” Ìdí nìyẹn tí ó fi pe ibẹ̀ ní Baali-pérásímù.*+ 21 Àwọn Filísínì fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sì kó wọn lọ.
22 Nígbà tó yá, àwọn Filísínì tún wá, wọ́n sì dúró káàkiri Àfonífojì* Réfáímù.+ 23 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, àmọ́ Ó sọ pé: “Má ṣe dojú kọ wọ́n ní tààràtà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yìn ni kí o gbà yọ sí wọn, kí o sì wá dojú kọ wọ́n níwájú àwọn igi bákà. 24 Tí o bá ti gbọ́ ìró tó ń dún bí ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi bákà, kí o gbé ìgbésẹ̀ ní kíá, nítorí Jèhófà yóò ti lọ ṣáájú rẹ láti ṣá àwọn ọmọ ogun Filísínì balẹ̀.” 25 Torí náà, Dáfídì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́, ó sì pa àwọn Filísínì+ láti Gébà+ títí dé Gésérì.+
6 Dáfídì tún kó gbogbo àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tó jẹ́ akọni jọ, wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) ọkùnrin. 2 Dáfídì àti gbogbo àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá lọ sí Baale-júdà kí wọ́n lè gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́+ wá láti ibẹ̀, iwájú rẹ̀ ni àwọn èèyàn ti ń ké pe orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ ẹni tó ń jókòó lórí* àwọn kérúbù.+ 3 Àmọ́ wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sórí kẹ̀kẹ́ tuntun,+ kí wọ́n lè fi gbé e láti ilé Ábínádábù,+ tó wà lórí òkè; Úsà àti Áhíò, àwọn ọmọ Ábínádábù, sì ń darí kẹ̀kẹ́ tuntun náà.
4 Nítorí náà, wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ láti ilé Ábínádábù tó wà lórí òkè, Áhíò sì ń rìn lọ níwájú Àpótí náà. 5 Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì ń ṣe ayẹyẹ níwájú Jèhófà pẹ̀lú onírúurú ohun ìkọrin tí a fi igi júnípà ṣe pẹ̀lú háàpù àti àwọn ohun ìkọrin míì tó ní okùn tín-ín-rín+ àti ìlù tanboríìnì+ àti sítírọ́mù pẹ̀lú síńbálì.*+ 6 Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Nákónì, Úsà na ọwọ́ rẹ̀ kí ó lè gbá Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ mú,+ torí màlúù náà mú kí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dojú dé. 7 Ni ìbínú Jèhófà bá ru sí Úsà, Ọlọ́run tòótọ́ pa á + níbẹ̀ nítorí ìwà àìlọ́wọ̀+ tí ó hù, ó sì kú síbẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ Àpótí Ọlọ́run tòótọ́. 8 Àmọ́ inú bí Dáfídì* nítorí pé ìbínú Jèhófà ru sí Úsà; wọ́n sì wá ń pe ibẹ̀ ní Peresi-úsà* títí di òní yìí. 9 Torí náà, ẹ̀rù Jèhófà+ ba Dáfídì ní ọjọ́ yẹn, ó sì sọ pé: “Kí ló dé tí a ó fi gbé Àpótí Jèhófà wá sọ́dọ̀ mi?”+ 10 Dáfídì kò fẹ́ gbé Àpótí Jèhófà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, Dáfídì ní kí wọ́n gbé e lọ sí ilé Obedi-édómù+ ará Gátì.
11 Oṣù mẹ́ta ni Àpótí Jèhófà fi wà ní ilé Obedi-édómù ará Gátì, Jèhófà sì ń bù kún Obedi-édómù àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.+ 12 Wọ́n ròyìn fún Ọba Dáfídì pé: “Jèhófà ti bù kún ilé Obedi-édómù àti gbogbo ohun ìní rẹ̀ nítorí Àpótí Ọlọ́run tòótọ́.” Torí náà, tayọ̀tayọ̀+ ni Dáfídì lọ gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ láti ilé Obedi-édómù wá sí Ìlú Dáfídì. 13 Nígbà tí àwọn tó ń ru+ Àpótí Jèhófà gbé ẹsẹ̀ mẹ́fà, ó fi akọ màlúù kan àti ẹran àbọ́sanra kan rúbọ.
14 Dáfídì ń fi gbogbo ara jó yí ká níwájú Jèhófà; ní gbogbo àkókò náà, Dáfídì wọ* éfódì+ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀* ṣe. 15 Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì ń gbé Àpótí+ Jèhófà bọ̀ pẹ̀lú igbe ayọ̀+ àti ìró ìwo.+ 16 Àmọ́ nígbà tí Àpótí Jèhófà wọ Ìlú Dáfídì, Míkálì,+ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù, bojú wolẹ̀ láti ojú fèrèsé,* ó rí Ọba Dáfídì tó ń fò sókè, tó ń jó yí ká níwájú Jèhófà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pẹ̀gàn rẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀.+ 17 Torí náà, wọ́n gbé Àpótí Jèhófà wọlé, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sí àyè rẹ̀ nínú àgọ́ tí Dáfídì pa fún un.+ Lẹ́yìn náà, Dáfídì rú àwọn ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ níwájú Jèhófà.+ 18 Nígbà tí Dáfídì parí rírú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó fi orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun súre fún àwọn èèyàn náà. 19 Láfikún sí i, ó pín búrẹ́dì tí ó rí bí òrùka àti ìṣù èso déètì àti ìṣù èso àjàrà gbígbẹ fún gbogbo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì, ó fún kálukú wọn lọ́kùnrin lóbìnrin, lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn náà gbéra, kálukú sì lọ sí ilé rẹ̀.
20 Nígbà tí Dáfídì pa dà láti súre fún agbo ilé rẹ̀, Míkálì,+ ọmọ Sọ́ọ̀lù, jáde wá pàdé rẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ wo bí ọba Ísírẹ́lì ti ṣe ara rẹ̀ lógo tó lónìí nígbà tí ó ṣí ara rẹ̀ sílẹ̀ lójú àwọn ẹrúbìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, bí àwọn akúrí ṣe máa ń ṣí ara sílẹ̀!”+ 21 Ni Dáfídì bá sọ fún Míkálì pé: “Iwájú Jèhófà ni mo ti ń ṣe àjọyọ̀, òun ni ó yàn mí dípò bàbá rẹ àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ láti fi mí ṣe aṣáájú Ísírẹ́lì+ tó jẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà. Torí náà, màá ṣe àjọyọ̀ níwájú Jèhófà, 22 màá túbọ̀ rẹ ara mi sílẹ̀ ju báyìí, màá sì di ẹni rírẹlẹ̀ ní ojú ara mi. Àmọ́ àwọn ẹrúbìnrin tí o mẹ́nu kàn yìí ni màá fi ṣe ara mi lógo.” 23 Nítorí náà, Míkálì,+ ọmọ Sọ́ọ̀lù, kò bímọ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.
7 Nígbà tí ọba ti ń gbé inú ilé* rẹ̀,+ tí Jèhófà sì ti fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó yí i ká, 2 ọba sọ fún wòlíì Nátánì+ pé: “Mò ń gbé inú ilé tí wọ́n fi igi kédárì kọ́+ nígbà tí Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wà láàárín àwọn aṣọ àgọ́.”+ 3 Nátánì dá ọba lóhùn pé: “Lọ ṣe ohunkóhun tó wà lọ́kàn rẹ, nítorí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.”+
4 Lóru ọjọ́ yẹn, Jèhófà bá Nátánì sọ̀rọ̀, ó ní: 5 “Lọ sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ṣé ìwọ ló máa kọ́ ilé tí màá máa gbé + fún mi ni? 6 Nítorí mi ò gbé inú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì títí di òní yìí,+ àmọ́ mò ń lọ* káàkiri nínú àgọ́ àti nínú àgọ́ ìjọsìn.+ 7 Ní gbogbo àkókò tí mò ń bá gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn, ṣé mo fìgbà kankan sọ fún ọ̀kan lára àwọn olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí mo yàn láti máa bójú tó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí àgùntàn, pé, ‘Kí ló dé tí ẹ ò fi kọ́ ilé onígi kédárì fún mi?’”’ 8 Ní báyìí, sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo mú ọ láti ibi ìjẹko, pé kí o má da agbo ẹran mọ́,+ kí o lè wá di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+ 9 Màá wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí o bá lọ,+ màá sì mú* gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ;+ màá jẹ́ kí orúkọ rẹ lókìkí gan-an+ bí orúkọ àwọn ẹni ńlá tó wà láyé. 10 Màá yan ibì kan fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì, màá fìdí wọn kalẹ̀, wọ́n á sì máa gbé ibẹ̀ láìsí ìyọlẹ́nu mọ́; àwọn ẹni burúkú kò ní pọ́n wọn lójú mọ́, bí wọ́n ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀,+ 11 láti ọjọ́ tí mo ti yan àwọn onídàájọ́+ fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì. Màá sì fún ọ ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.+
“‘“Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà sọ fún ọ pé, Jèhófà yóò kọ́ ilé fún ọ.*+ 12 Nígbà tí o bá kú,+ tí o sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ, nígbà náà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọmọ ìwọ fúnra rẹ,* màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+ 13 Òun ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ màá sì fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.+ 14 Màá di bàbá rẹ̀, á sì di ọmọ mi.+ Tí ó bá ṣe àìtọ́, màá fi ọ̀pá àti ẹgba àwọn ọmọ aráyé*+ bá a wí. 15 Ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀ bí mo ṣe mú un kúrò lára Sọ́ọ̀lù,+ ẹni tí mo mú kúrò níwájú rẹ. 16 Ilé rẹ àti ìjọba rẹ máa fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí láé níwájú rẹ; ìtẹ́ rẹ á sì fìdí múlẹ̀ títí láé.”’”+
17 Nátánì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí àti gbogbo ìran tó rí+ fún Dáfídì.
18 Ni Ọba Dáfídì bá wọlé, ó jókòó níwájú Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ta ni mí? Kí ni ilé mi sì já mọ́ tí o fi mú mi dé ibi tí mo dé yìí?+ 19 Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, o tún sọ nípa ilé ìránṣẹ́ rẹ títí lọ dé ọjọ́ iwájú tó jìnnà; èyí sì jẹ́ ìtọ́ni* fún gbogbo aráyé, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 20 Kí ni Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ tún lè sọ fún ọ nígbà tó jẹ́ pé o mọ̀ mí dáadáa,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ? 21 Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ àti nítorí ohun tó wà lọ́kàn rẹ* ni o fi ṣe gbogbo àwọn ohun ńlá yìí, tí o sì jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ+ mọ̀ nípa wọn. 22 Ìdí nìyẹn tí o fi tóbi gan-an,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. Kò sí ẹni tó dà bí rẹ,+ kò sì sí Ọlọ́run kankan àfi ìwọ;+ gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́ jẹ́rìí sí i. 23 Orílẹ̀-èdè wo ní gbogbo ayé ló dà bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì?+ Ọlọ́run lọ rà wọ́n pa dà nítorí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀,+ ó sì ṣe orúkọ fún ara rẹ̀+ bí ó ṣe ń ṣe àwọn ohun ńlá àti àwọn ohun àgbàyanu fún wọn.+ O lé àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọlọ́run wọn jáde nítorí àwọn èèyàn rẹ, tí o rà pa dà fún ara rẹ láti Íjíbítì. 24 O fìdí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì múlẹ̀ láti máa jẹ́ àwọn èèyàn rẹ títí lọ;+ ìwọ Jèhófà sì di Ọlọ́run wọn.+
25 “Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run, mú ìlérí tí o ṣe nípa ìránṣẹ́ rẹ àti nípa ilé rẹ̀ ṣẹ títí láé, kí o sì ṣe ohun tí o ṣèlérí.+ 26 Kí a gbé orúkọ rẹ ga títí láé,+ kí àwọn èèyàn lè sọ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì,’ kí ilé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ sì fìdí múlẹ̀ níwájú rẹ.+ 27 Nítorí ìwọ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti fi han ìránṣẹ́ rẹ pé, ‘Màá kọ́ ilé fún ọ.’*+ Ìdí nìyẹn tí ìránṣẹ́ rẹ fi ní ìgboyà* láti gba àdúrà yìí sí ọ. 28 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́, òtítọ́+ ni ọ̀rọ̀ rẹ, o sì ti ṣèlérí àwọn ohun rere yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. 29 Nítorí náà, jẹ́ kí ó dùn mọ́ ọ nínú láti bù kún ilé ìránṣẹ́ rẹ, sì jẹ́ kí ó máa wà títí láé níwájú rẹ;+ nítorí ìwọ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti ṣèlérí, sì jẹ́ kí ìbùkún rẹ máa wà lórí ilé ìránṣẹ́ rẹ títí láé.”+
8 Nígbà tó yá, Dáfídì ṣẹ́gun àwọn Filísínì,+ ó borí wọn,+ Dáfídì sì gba Metegi-ámà lọ́wọ́ àwọn Filísínì.
2 Ó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Móábù,+ ó dá wọn dùbúlẹ̀, ó sì fi okùn wọ̀n wọ́n. Ó ní kí wọ́n pa àwọn tó wà níbi tí okùn ìwọ̀n méjì gùn dé, àmọ́ kí wọ́n dá àwọn tó wà níbi okùn ìwọ̀n kan sí.+ Àwọn ọmọ Móábù di ìránṣẹ́ Dáfídì, wọ́n sì ń mú ìṣákọ́lẹ̀*+ wá.
3 Dáfídì ṣẹ́gun Hadadésà ọmọ Réhóbù ọba Sóbà+ bí ó ṣe ń lọ láti gba àkóso rẹ̀ pa dà ní odò Yúfírétì.+ 4 Dáfídì gba ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje (1,700) agẹṣin àti ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn lọ́wọ́ rẹ̀. Dáfídì sì já iṣan ẹsẹ̀* gbogbo àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ogun, àmọ́ ó dá ọgọ́rùn-ún (100) lára àwọn ẹṣin+ náà sí.
5 Nígbà tí àwọn ará Síríà tó wà ní Damásíkù+ wá ran Hadadésà ọba Sóbà lọ́wọ́, Dáfídì pa ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) lára àwọn ará Síríà+ náà. 6 Lẹ́yìn náà, Dáfídì fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí Damásíkù ní Síríà, àwọn ará Síríà wá di ìránṣẹ́ Dáfídì, wọ́n sì ń mú ìṣákọ́lẹ̀* wá. Jèhófà sì ń jẹ́ kí Dáfídì ṣẹ́gun* ní ibikíbi tó bá lọ.+ 7 Láfikún sí i, Dáfídì gba àwọn apata* wúrà tó wà lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà, ó sì kó wọn wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 8 Ọba Dáfídì kó bàbà tó pọ̀ gan-an láti Bétà àti Bérótáì, àwọn ìlú Hadadésà.
9 Lásìkò yìí, Tóì ọba Hámátì+ gbọ́ pé Dáfídì ti ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadésà.+ 10 Torí náà, Tóì rán Jórámù ọmọkùnrin rẹ̀ sí Ọba Dáfídì pé kí ó lọ béèrè àlàáfíà rẹ̀, kí ó sì bá a yọ̀ torí pé ó ti bá Hadadésà jà, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ (nítorí Hadadésà ti máa ń bá Tóì jà tẹ́lẹ̀), ó sì kó àwọn ohun èlò fàdákà, ohun èlò wúrà àti ohun èlò bàbà wá. 11 Ọba Dáfídì yà wọ́n sí mímọ́ fún Jèhófà bó ṣe ya fàdákà àti wúrà tó kó lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ṣẹ́gun+ sí mímọ́: 12 ó kó wọn láti Síríà àti Móábù,+ látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, àwọn Filísínì+ àti àwọn ọmọ Ámálékì+ àti látinú ẹrù ogun Hadadésà+ ọmọ Réhóbù ọba Sóbà. 13 Òkìkí Dáfídì túbọ̀ kàn nígbà tí ó pa dà láti ibi tó ti lọ pa ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) lára àwọn ọmọ Édómù ní Àfonífojì Iyọ̀.+ 14 Ó fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí Édómù. Gbogbo Édómù ni ó fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí, gbogbo àwọn ọmọ Édómù sì di ìránṣẹ́ Dáfídì.+ Jèhófà sì ń jẹ́ kí Dáfídì ṣẹ́gun* ní ibikíbi tó bá lọ.+
15 Dáfídì ń jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì,+ Dáfídì ń dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó sì ń ṣe òdodo+ sí gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.+ 16 Jóábù+ ọmọ Seruáyà ni olórí àwọn ọmọ ogun, Jèhóṣáfátì+ ọmọ Áhílúdù sì ni akọ̀wé ìrántí. 17 Sádókù+ ọmọ Áhítúbù àti Áhímélékì ọmọ Ábíátárì ni àlùfáà, Seráyà sì ni akọ̀wé. 18 Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà ni olórí àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì.+ Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì di olórí àwọn òjíṣẹ́.*
9 Nígbà náà, Dáfídì sọ pé: “Ṣé ẹnì kankan ṣì kù ní ilé Sọ́ọ̀lù tí mo lè fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí nítorí Jónátánì?”+ 2 Ìránṣẹ́ ilé Sọ́ọ̀lù kan wà tó ń jẹ́ Síbà.+ Torí náà, wọ́n pè é wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ìwọ ni Síbà?” Ó dáhùn pé: “Èmi ìránṣẹ́ rẹ ni.” 3 Ọba ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ṣé ẹnì kankan ṣì kù ní ilé Sọ́ọ̀lù tí mo lè nawọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ sí?” Síbà dá ọba lóhùn pé: “Ọmọkùnrin Jónátánì kan ṣì wà; ó rọ ní ẹsẹ̀ méjèèjì.”*+ 4 Ọba wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ibo ló wà?” Síbà dá ọba lóhùn pé: “Ó wà ní ilé Mákírù+ ọmọkùnrin Ámíélì ní Lo-débà.”
5 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ọba Dáfídì ní kí wọ́n lọ mú un wá láti ilé Mákírù ọmọ Ámíélì ní Lo-débà. 6 Nígbà tí Méfíbóṣétì ọmọ Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù wọlé sọ́dọ̀ Dáfídì, ní kíá, ó tẹrí ba, ó sì wólẹ̀. Dáfídì bá sọ pé: “Méfíbóṣétì!” Ó sì dáhùn pé: “Ìránṣẹ́ rẹ nìyí.” 7 Dáfídì sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, màá rí i dájú pé mo fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀+ hàn sí ọ nítorí Jónátánì bàbá rẹ, màá dá gbogbo ilẹ̀ Sọ́ọ̀lù bàbá rẹ àgbà pa dà fún ọ, orí tábìlì mi + ni wàá sì ti máa jẹun* nígbà gbogbo.”
8 Ni ó bá wólẹ̀, ó sì sọ pé: “Kí ni èmi ìránṣẹ́ rẹ já mọ́, tí o fi yí ojú* rẹ sí òkú ajá+ bíi tèmi?” 9 Ọba wá ránṣẹ́ pe Síbà, ẹmẹ̀wà* Sọ́ọ̀lù, ó sì sọ fún un pé: “Gbogbo ohun tí Sọ́ọ̀lù àti gbogbo ilé rẹ̀ ní ni mo fún ọmọ ọmọ ọ̀gá rẹ.+ 10 Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni á máa bá a dá oko, wàá máa kó irè oko jọ láti pèsè oúnjẹ tí àwọn ará ilé ọmọ ọmọ ọ̀gá rẹ á máa jẹ. Àmọ́ orí tábìlì mi+ ni Méfíbóṣétì, ọmọ ọmọ ọ̀gá rẹ, á ti máa jẹun nígbà gbogbo.”
Síbà ní ọmọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) àti ogún (20) ìránṣẹ́.+ 11 Nígbà náà, Síbà sọ fún ọba pé: “Gbogbo ohun tí olúwa mi ọba pa láṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ ni ìránṣẹ́ rẹ máa ṣe.” Torí náà, Méfíbóṣétì máa ń jẹun lórí tábìlì Dáfídì* bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọba. 12 Méfíbóṣétì tún ní ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Máíkà;+ gbogbo àwọn tó ń gbé ní ilé Síbà sì di ìránṣẹ́ Méfíbóṣétì. 13 Méfíbóṣétì ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, nítorí ó ń jẹun nígbà gbogbo lórí tábìlì ọba;+ ó sì rọ ní ẹsẹ̀ méjèèjì.+
10 Nígbà tó yá, ọba àwọn ọmọ Ámónì+ kú, Hánúnì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+ 2 Dáfídì bá sọ pé: “Màá fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Hánúnì ọmọ Náháṣì, bí bàbá rẹ̀ ṣe fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi.” Torí náà, Dáfídì rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti lọ tù ú nínú nítorí bàbá rẹ̀ tó kú. Àmọ́ nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì dé ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì, 3 àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Ámónì sọ fún Hánúnì olúwa wọn pé: “Ṣé o rò pé torí kí Dáfídì lè bọlá fún bàbá rẹ ló ṣe rán àwọn olùtùnú sí ọ? Ǹjẹ́ kì í ṣe torí kí Dáfídì lè wo inú ìlú yìí, kí ó ṣe amí rẹ̀, kí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ ló ṣe rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí ọ?” 4 Nítorí náà, Hánúnì mú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ó fá apá kan irùngbọ̀n+ wọn dà nù, ó gé ẹ̀wù wọn ní ààbọ̀ dé ìdí, ó sì ní kí wọ́n máa lọ. 5 Nígbà tí Dáfídì gbọ́, kíá ló rán àwọn ọkùnrin kan lọ pàdé wọn, nítorí wọ́n ti dójú ti àwọn ọkùnrin náà gan-an; ọba sì sọ fún wọn pé: “Ẹ dúró sí Jẹ́ríkò+ títí irùngbọ̀n yín á fi hù pa dà, lẹ́yìn náà kí ẹ pa dà wálé.”
6 Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ámónì rí i pé àwọn ti di ẹni ìkórìíra lójú Dáfídì, torí náà àwọn ọmọ Ámónì ránṣẹ́ sí àwọn ará Síríà tó wà ní Bẹti-réhóbù+ àti àwọn ará Síríà tó wà ní Sóbà,+ wọ́n sì háyà ọ̀kẹ́ kan (20,000) àwọn ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn lọ́dọ̀ wọn; àti lọ́dọ̀ ọba Máákà,+ ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ọkùnrin; àti láti Íṣítóbù,* ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ọkùnrin.+ 7 Nígbà tí Dáfídì gbọ́, ó rán Jóábù lọ àti gbogbo àwọn ọmọ ogun títí kan àwọn jagunjagun rẹ̀ tó lákíkanjú+ jù lọ. 8 Àwọn ọmọ Ámónì jáde lọ, wọ́n sì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ní àtiwọ ẹnubodè ìlú, àmọ́ àwọn ará Síríà tó wà ní Sóbà àti ní Réhóbù pẹ̀lú Íṣítóbù* àti Máákà wà lórí pápá.
9 Nígbà tí Jóábù rí i pé wọ́n ń gbé ogun bọ̀ níwájú àti lẹ́yìn, ó yan lára àwọn ọmọ ogun tó dára jù lọ ní Ísírẹ́lì, ó sì tò wọ́n lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti pàdé àwọn ará Síríà.+ 10 Ó fi àwọn tó kù lára àwọn ọkùnrin náà sábẹ́ àṣẹ* Ábíṣáì+ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, kí ó lè tò wọ́n lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti pàdé àwọn ọmọ Ámónì.+ 11 Ó wá sọ pé: “Tí ọwọ́ àwọn ará Síríà bá le jù fún mi, kí o wá gbà mí sílẹ̀; àmọ́ tí ọwọ́ àwọn ọmọ Ámónì bá le jù fún ọ, màá wá gbà ọ́ sílẹ̀. 12 Kí a jẹ́ alágbára, kí a sì ní ìgboyà+ nítorí àwọn èèyàn wa àti àwọn ìlú Ọlọ́run wa, Jèhófà yóò sì ṣe ohun tó dára ní ojú rẹ̀.”+
13 Ìgbà náà ni Jóábù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ jáde lọ pàdé àwọn ará Síríà lójú ogun, wọ́n sì sá kúrò níwájú rẹ̀.+ 14 Nígbà tí àwọn ọmọ Ámónì rí i pé àwọn ará Síríà ti fẹsẹ̀ fẹ, àwọn náà sá kúrò níwájú Ábíṣáì, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Lẹ́yìn náà, Jóábù pa dà látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, ó sì wá sí Jerúsálẹ́mù.
15 Nígbà tí àwọn ará Síríà rí i pé Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn, wọ́n túnra mú.+ 16 Nítorí náà, Hadadésà+ ránṣẹ́ sí àwọn ará Síríà tó wà ní agbègbè Odò,*+ lẹ́yìn náà, wọ́n wá sí Hélámù, Ṣóbákì olórí àwọn ọmọ ogun Hadadésà ló sì ń darí wọn.
17 Nígbà tí wọ́n ròyìn fún Dáfídì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, ó sọdá Jọ́dánì, ó sì wá sí Hélámù. Ìgbà náà ni àwọn ará Síríà to ara wọn lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti pàdé Dáfídì, wọ́n sì bá a jà.+ 18 Àmọ́, àwọn ará Síríà sá kúrò níwájú Ísírẹ́lì; Dáfídì sì pa ọgọ́rùn-ún méje (700) àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) àwọn agẹṣin ará Síríà, ó ṣá Ṣóbákì olórí àwọn ọmọ ogun wọn balẹ̀, ó sì kú síbẹ̀.+ 19 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba àti àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà rí i pé Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn, wọ́n tètè wá àlàáfíà lọ́dọ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n sì di ọmọ abẹ́ wọn;+ ẹ̀rù wá ń ba àwọn ará Síríà láti tún ran àwọn ọmọ Ámónì lọ́wọ́.
11 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún,* lákòókò tí àwọn ọba máa ń jáde ogun, Dáfídì rán Jóábù àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì pé kí wọ́n lọ pa àwọn ọmọ Ámónì run, wọ́n sì dó ti Rábà,+ àmọ́ Dáfídì dúró sí Jerúsálẹ́mù.+
2 Nírọ̀lẹ́ ọjọ́* kan, Dáfídì dìde lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì ń rìn lórí òrùlé ilé* ọba. Láti orí òrùlé náà, ó rí obìnrin kan tó ń wẹ̀, obìnrin náà sì rẹwà gan-an. 3 Dáfídì rán ẹnì kan láti lọ wádìí nípa obìnrin náà, ẹni náà sì wá jábọ̀ pé: “Ṣebí Bátí-ṣébà+ ọmọ Élíámù+ ìyàwó Ùráyà+ ọmọ Hétì ni.”+ 4 Lẹ́yìn náà, Dáfídì ní kí àwọn òjíṣẹ́ lọ mú un wá.+ Torí náà, ó wọlé wá bá a, ó sì bá a sùn.+ (Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí obìnrin náà ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ohun àìmọ́*+ rẹ̀.) Lẹ́yìn náà, ó pa dà sílé rẹ̀.
5 Obìnrin náà lóyún, ó sì ránṣẹ́ sí Dáfídì pé: “Mo ti lóyún.” 6 Ni Dáfídì bá ránṣẹ́ sí Jóábù pé: “Rán Ùráyà ọmọ Hétì sí mi.” Torí náà, Jóábù rán Ùráyà sí Dáfídì. 7 Nígbà tí Ùráyà dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Dáfídì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí Jóábù ṣe ń ṣe sí àti bí àwọn ọmọ ogun ṣe ń ṣe sí, ó sì tún béèrè bí ogun náà ṣe ń lọ sí. 8 Dáfídì wá sọ fún Ùráyà pé: “Lọ sí ilé rẹ, kí o lọ sinmi.”* Nígbà tí Ùráyà kúrò ní ilé ọba, ọba fi ẹ̀bùn* ránṣẹ́ sí i. 9 Àmọ́, Ùráyà sùn sí ẹnu ọ̀nà ilé ọba pẹ̀lú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì lọ sí ilé rẹ̀. 10 Torí náà, wọ́n sọ fún Dáfídì pé: “Ùráyà kò lọ sí ilé rẹ̀ o.” Dáfídì wá sọ fún Ùráyà pé: “Ṣebí o ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ìrìn àjò ni? Kí ló dé tí o ò lọ sí ilé rẹ?” 11 Ùráyà dá Dáfídì lóhùn pé: “Àpótí + àti gbogbo ọmọ ogun Ísírẹ́lì àti ti Júdà ń gbé lábẹ́ àtíbàbà, olúwa mi Jóábù àti àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi sì pàgọ́ sórí pápá. Ṣé ó wá yẹ kí n lọ sínú ilé mi láti jẹ àti láti mu àti láti bá ìyàwó mi sùn?+ Bí o ti wà láàyè, tí o sì ń mí,* mi ò jẹ́ ṣe nǹkan yìí!”
12 Dáfídì wá sọ fún Ùráyà pé: “Tún dúró síbí lónìí, tó bá sì di ọ̀la, màá jẹ́ kí o máa lọ.” Nítorí náà, Ùráyà dúró sí Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ yẹn àti ní ọjọ́ kejì. 13 Lẹ́yìn náà, Dáfídì ní kí wọ́n lọ pè é wá, kí ó wá bá òun jẹun, kí ó sì mu, ni ó bá rọ ọ́ yó. Àmọ́ nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, ó lọ sùn sórí ibùsùn rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì lọ sí ilé rẹ̀. 14 Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, Dáfídì kọ lẹ́tà kan sí Jóábù, ó sì fi rán Ùráyà. 15 Ó kọ ọ́ sínú lẹ́tà náà pé: “Ẹ fi Ùráyà síwájú níbi tí ogun ti le jù lọ. Lẹ́yìn náà kí ẹ pa dà lẹ́yìn rẹ̀, kí wọ́n lè mú un balẹ̀, kí ó sì kú.”+
16 Jóábù ti ń ṣọ́ ìlú náà lójú méjèèjì, ó wá fi Ùráyà sí ibi tí ó mọ̀ pé àwọn jagunjagun tó lákíkanjú wà. 17 Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà jáde wá bá Jóábù jà, àwọn kan lára ìránṣẹ́ Dáfídì kú, Ùráyà ọmọ Hétì sì wà lára àwọn tó kú.+ 18 Jóábù wá ránṣẹ́ sí Dáfídì láti ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú ogun fún un. 19 Ó sọ fún òjíṣẹ́ náà pé: “Tí o bá ti ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú ogun fún ọba tán, 20 ọba lè bínú, kí ó sọ fún ọ pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi sún mọ́ ìlú náà tó bẹ́ẹ̀ láti jà? Ṣé ẹ ò mọ̀ pé wọ́n máa ta ọfà láti orí ògiri ni? 21 Àbí, ta ló pa Ábímélékì+ ọmọ Jerubéṣétì?*+ Ṣé kì í ṣe obìnrin ló ju ọlọ lù ú láti orí ògiri tí ó fi kú ní Tébésì? Kí ló dé tí ẹ fi sún mọ́ ògiri náà tó bẹ́ẹ̀?’ Kí o wá sọ pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ Ùráyà ọmọ Hétì náà kú.’”
22 Nítorí náà, òjíṣẹ́ náà lọ sọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì sọ gbogbo ohun tí Jóábù ní kó sọ. 23 Ìgbà náà ni òjíṣẹ́ náà sọ fún Dáfídì pé: “Àwọn ọkùnrin náà lágbára jù wá lọ, wọ́n jáde láti bá wa jà ní pápá; àmọ́ a lé wọn pa dà síbi àtiwọ ẹnubodè ìlú. 24 Àwọn tafàtafà sì ń ta àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ́fà láti orí ògiri, àwọn kan lára ìránṣẹ́ ọba kú; ìránṣẹ́ rẹ Ùráyà ọmọ Hétì náà sì kú.”+ 25 Ni Dáfídì bá sọ fún òjíṣẹ́ náà pé: “Sọ fún Jóábù pé: ‘Má ṣe jẹ́ kí ọ̀ràn yìí dà ọ́ láàmú, kò sẹ́ni tí idà ò lè pa lójú ogun. Túbọ̀ múra sí ìjà tí ò ń bá ìlú náà jà, kí o sì ṣẹ́gun rẹ̀.’+ Kí o bá mi fún Jóábù ní ìṣírí.”
26 Nígbà tí ìyàwó Ùráyà gbọ́ pé Ùráyà ọkọ òun ti kú, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀ ọkọ rẹ̀. 27 Gbàrà tí àkókò ọ̀fọ̀ náà parí, Dáfídì ránṣẹ́ sí i, ó mú un wá sí ilé rẹ̀, ó di ìyàwó rẹ̀,+ ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un. Àmọ́ ohun tí Dáfídì ṣe yìí bí Jèhófà nínú* gan-an.+
12 Nítorí náà, Jèhófà rán Nátánì+ sí Dáfídì. Ó wọlé wá bá a,+ ó sì sọ pé: “Àwọn ọkùnrin méjì wà nínú ìlú kan, ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ aláìní. 2 Ọlọ́rọ̀ náà ní àgùntàn àti màlúù tó pọ̀ gan-an;+ 3 ṣùgbọ́n ọkùnrin aláìní náà kò ní nǹkan kan àfi abo ọ̀dọ́ àgùntàn kan tí ó rà.+ Ó ń tọ́jú rẹ̀, ó sì ń dàgbà lọ́dọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀. Ó máa ń jẹ lára oúnjẹ díẹ̀ tí ọkùnrin náà ní, á mu látinú ife rẹ̀, àyà rẹ̀ ló sì ń sùn sí. Ó wá dà bí ọmọbìnrin fún un. 4 Nígbà tó yá, àlejò kan dé sọ́dọ̀ ọlọ́rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kò mú lára àwọn àgùntàn àti màlúù rẹ̀ láti fi se oúnjẹ fún arìnrìn-àjò tí ó dé sọ́dọ̀ rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, abo ọ̀dọ́ àgùntàn ọkùnrin aláìní yẹn ló lọ mú, ó sì pa á fún ọkùnrin tí ó dé sọ́dọ̀ rẹ̀.”+
5 Inú bí Dáfídì gan-an sí ọkùnrin náà, ó sì sọ fún Nátánì pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè,+ ikú tọ́ sí ọkùnrin tó ṣe irú èyí! 6 Ó sì yẹ kó san ìlọ́po mẹ́rin+ abo ọ̀dọ́ àgùntàn náà, nítorí ohun tó ṣe yìí àti nítorí pé kò lójú àánú.”
7 Ìgbà náà ni Nátánì sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ ni ọkùnrin náà! Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Èmi ni mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì,+ mo sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù.+ 8 Tinútinú ni mo fún ọ ní ilé ọ̀gá rẹ,+ tí mo fi àwọn ìyàwó ọ̀gá rẹ+ lé ọ lọ́wọ́, mo sì fún ọ ní ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà.+ Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, mo tún fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i fún ọ.+ 9 Kí ló dé tí o kò fi ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sí, tí o wá ṣe ohun tó burú lójú rẹ̀? O fi idà pa+ Ùráyà ọmọ Hétì! Lẹ́yìn náà, o sọ ìyàwó rẹ̀ di tìrẹ+ lẹ́yìn tí o ti mú kí idà àwọn ọmọ Ámónì pa á.+ 10 Wò ó, idà kò ní kúrò ní ilé rẹ láé,+ nítorí pé o kọ̀ mí, tí o sì sọ ìyàwó Ùráyà ọmọ Hétì di tìrẹ.’ 11 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Wò ó, màá mú kí àjálù bá ọ láti inú ilé ara rẹ;+ ojú rẹ ni màá ti gba àwọn ìyàwó rẹ,+ tí màá fi wọ́n fún ọkùnrin míì,* tí á sì bá wọn sùn ní ọ̀sán gangan.*+ 12 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìkọ̀kọ̀+ ni o ti ṣe é, iwájú gbogbo Ísírẹ́lì ni màá ti ṣe ohun tí mo sọ yìí ní ọ̀sán gangan.’”*
13 Dáfídì wá sọ fún Nátánì pé: “Mo ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.”+ Nátánì dá Dáfídì lóhùn pé: “Jèhófà, ní tirẹ̀ ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.*+ O ò ní kú.+ 14 Síbẹ̀, nítorí pé ohun tí o ṣe yìí fi hàn pé o ò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà rárá, ó dájú pé ọmọkùnrin tí obìnrin náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bí fún ọ, yóò kú.”
15 Lẹ́yìn náà, Nátánì gba ilé rẹ̀ lọ.
Jèhófà fi àrùn kọ lu ọmọ tí ìyàwó Ùráyà bí fún Dáfídì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn. 16 Dáfídì bẹ Ọlọ́run tòótọ́ nítorí ọmọ náà. Dáfídì gba ààwẹ̀ tó le, ó sì máa ń sùn sórí ilẹ̀ ní alaalẹ́.+ 17 Nítorí náà, àwọn àgbààgbà ilé rẹ̀ wá sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n fẹ́ gbé e dìde kúrò nílẹ̀, àmọ́ kò gbà, kò sì bá wọn jẹun. 18 Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà kú, àmọ́ ẹ̀rù ń ba àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì láti sọ fún un pé ọmọ náà ti kú. Wọ́n sọ pé: “A bá a sọ̀rọ̀ nígbà tí ọmọ náà ṣì wà láàyè, àmọ́ kò gbọ́ tiwa. Báwo ni a ṣe máa sọ fún un pé ọmọ náà ti kú? Ó lè lọ ṣe ohun tí á léwu gan-an.”
19 Nígbà tí Dáfídì rí i pé àwọn ìránṣẹ́ òun ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láàárín ara wọn, ó fi òye gbé e pé ọmọ náà ti kú. Dáfídì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ọmọ náà ti kú ni?” Wọ́n fèsì pé: “Ó ti kú.” 20 Torí náà, Dáfídì dìde nílẹ̀. Ó lọ wẹ̀, ó fi òróró para,+ ó pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó lọ sí ilé+ Jèhófà, ó sì wólẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé* rẹ̀, ó ní kí wọ́n gbé oúnjẹ wá fún òun, ó sì jẹun. 21 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí nìdí tí o fi ṣe ohun tí o ṣe yìí? Nígbà tí ọmọ náà ṣì wà láàyè, o gbààwẹ̀, o sì ń sunkún; àmọ́ gbàrà tí ọmọ náà kú, o dìde, o sì jẹun.” 22 Ó fèsì pé: “Nígbà tí ọmọ náà ṣì wà láàyè, mo gbààwẹ̀,+ mo sì ń sunkún torí mo sọ fún ara mi pé, ‘Ta ló mọ̀ bóyá Jèhófà lè ṣojú rere sí mi, kó sì jẹ́ kí ọmọ náà yè?’+ 23 Ní báyìí tí ó ti kú, ṣé ó tún yẹ kí n máa gbààwẹ̀? Ṣé mo lè dá a pa dà ni?+ Èmi ni màá lọ bá a,+ àmọ́ kò lè wá bá mi.”+
24 Nígbà náà, Dáfídì tu Bátí-ṣébà+ ìyàwó rẹ̀ nínú. Ó wọlé lọ bá a, ó sì bá a ní àṣepọ̀. Nígbà tó yá, ó bí ọmọkùnrin kan, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Sólómọ́nì.*+ Jèhófà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ 25 ó rán wòlíì Nátánì+ kí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jedidáyà,* nítorí Jèhófà.
26 Jóábù ń bá Rábà+ ìlú àwọn ọmọ Ámónì+ jà nìṣó, ó sì gba ìlú ọba.*+ 27 Nítorí náà, Jóábù rán àwọn òjíṣẹ́ sí Dáfídì, ó sọ pé: “Mo ti bá Rábà+ jà, mo sì ti gba ìlú omi.* 28 Ní báyìí, kó àwọn ọmọ ogun tó ṣẹ́ kù jọ, kí o dó ti ìlú náà, kí o sì gbà á. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, èmi ni màá gba ìlú náà, wọ́n á sì máa yìn mí pé èmi ni mo gbà á.”*
29 Nítorí náà, Dáfídì kó gbogbo àwọn ọmọ ogun jọ, ó lọ sí Rábà, ó bá a jà, ó sì gbà á. 30 Nígbà náà, ó mú adé Málíkámù kúrò ní orí rẹ̀. Ìwọ̀n adé náà jẹ́ tálẹ́ńtì* wúrà kan, pẹ̀lú àwọn òkúta iyebíye, a sì fi dé Dáfídì lórí. Ó tún kó ẹrù+ tó pọ̀ gan-an látinú ìlú náà.+ 31 Ó kó àwọn èèyàn inú rẹ̀, ó fi wọ́n sídìí iṣẹ́ pé kí wọ́n máa fi ayùn rẹ́ òkúta, kí wọ́n máa fi àwọn ohun èlò onírin mímú àti àáké ṣiṣẹ́, kí wọ́n sì máa ṣe bíríkì. Ohun tó ṣe sí gbogbo àwọn ìlú àwọn ọmọ Ámónì nìyẹn. Níkẹyìn, Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ ogun náà pa dà sí Jerúsálẹ́mù.
13 Ábúsálómù ọmọ Dáfídì ní àbúrò obìnrin kan tó rẹwà, Támárì+ ni orúkọ rẹ̀, ìfẹ́ rẹ̀ sì ti kó sí Ámínónì+ ọmọ Dáfídì lórí. 2 Ámínónì dààmú nítorí Támárì àbúrò rẹ̀ obìnrin débi pé ó ń ṣàìsàn, torí pé wúńdíá* ni, ó sì dà bíi pé kò ṣeé ṣe fún Ámínónì láti ṣe ohun tí ó fẹ́ pẹ̀lú rẹ̀. 3 Ámínónì ní ọ̀rẹ́ kan tó ń jẹ́ Jèhónádábù,+ ọmọ Ṣímẹ́à,+ ẹ̀gbọ́n Dáfídì; Jèhónádábù sì gbọ́n féfé. 4 Torí náà, ó sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ìwọ ọmọ ọba fi ń banú jẹ́ láràárọ̀? O ò ṣe sọ fún mi?” Ámínónì dá a lóhùn pé: “Ìfẹ́ Támárì àbúrò+ Ábúsálómù arákùnrin mi ló kó sí mi lórí.” 5 Jèhónádábù wá fún un lésì pé: “Dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ, kí o sì ṣe bíi pé ara rẹ ò yá. Tí bàbá rẹ bá ti wá wò ọ́, sọ fún un pé, ‘Jọ̀ọ́, jẹ́ kí Támárì àbúrò mi wá fún mi ní oúnjẹ díẹ̀. Tó bá jẹ́ pé ojú mi ló ti ṣe oúnjẹ aláìsàn* náà, màá jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’”
6 Torí náà, Ámínónì dùbúlẹ̀, ó ṣe bíi pé ara òun kò yá, ọba sì wọlé wá wò ó. Ni Ámínónì bá sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Támárì àbúrò mi wá, kí ó sì ṣe kéèkì méjì tí ó rí bí ọkàn ní ìṣojú mi, kí n lè jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.” 7 Dáfídì bá ránṣẹ́ sí Támárì ní ilé pé: “Jọ̀wọ́ lọ sí ilé Ámínónì ẹ̀gbọ́n rẹ, kí o sì ṣe oúnjẹ* fún un.” 8 Nítorí náà, Támárì lọ sí ilé Ámínónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ níbi tó dùbúlẹ̀ sí. Ó mú ìyẹ̀fun tó fẹ́ fi ṣe kéèkì, ó pò ó ní ìṣojú rẹ̀, ó sì ṣe kéèkì náà. 9 Lẹ́yìn náà, ó gbé kéèkì náà kúrò nínú páànù, ó sì gbé oúnjẹ síwájú rẹ̀. Ṣùgbọ́n Ámínónì kò jẹun, ó sọ pé: “Gbogbo yín ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi!” Torí náà, gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
10 Ámínónì wá sọ fún Támárì pé: “Gbé oúnjẹ* náà wá sínú yàrá mi, kí n lè jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Torí náà, Támárì gbé kéèkì tó rí bí ọkàn tó ti ṣe wá fún Ámínónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nínú yàrá. 11 Nígbà tó gbé e wá fún un kó lè jẹ ẹ́, Ámínónì rá a mú, ó sì sọ pé: “Wá sùn tì mí, àbúrò mi.” 12 Àmọ́, ó sọ fún un pé: “Rárá o, ẹ̀gbọ́n mi! Má ṣe kó ẹ̀gàn bá mi, nítorí ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Ísírẹ́lì.+ Má ṣe ohun tó ń dójú tini yìí.+ 13 Ibo ni màá gbé ìtìjú yìí wọ̀? Ìwọ náà á sì di ẹni ẹ̀tẹ́ ní Ísírẹ́lì. Ní báyìí, jọ̀wọ́ bá ọba sọ̀rọ̀, kò ní ṣàì fi mí fún ọ.” 14 Àmọ́ kò gbọ́ tirẹ̀, ó fi agbára mú un, ó sì fipá bá a lò pọ̀. 15 Lẹ́yìn náà, Ámínónì bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra rẹ̀ burúkú-burúkú débi pé ìkórìíra tó ní sí i yìí wá ju ìfẹ́ tó ní sí i tẹ́lẹ̀. Ámínónì sọ fún un pé: “Dìde; máa lọ!” 16 Ni ó bá sọ fún un pé: “Rárá o, ẹ̀gbọ́n mi, bí o ṣe fẹ́ lé mi jáde yìí máa burú ju ohun tí o ṣe sí mi lọ!” Àmọ́ kò gbọ́ tirẹ̀.
17 Ni ó bá pe ọ̀dọ́kùnrin tó ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ó ní: “Jọ̀ọ́, mú ẹni yìí jáde kúrò níwájú mi, kí o sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn síta.” 18 (Àkànṣe aṣọ* ni Támárì wọ̀ ní àkókò yẹn, nítorí irú aṣọ yẹn ni àwọn wúńdíá ọmọ ọba máa ń wọ̀.) Nítorí náà, ìránṣẹ́ rẹ̀ mú un jáde, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn síta. 19 Ìgbà náà ni Támárì da eérú sórí,+ ó fa aṣọ àtàtà tó wọ̀ ya; ó káwọ́ lérí, ó sì bá tirẹ̀ lọ, ó ń sunkún bí ó ṣe ń lọ.
20 Ábúsálómù+ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé Ámínónì ẹ̀gbọ́n rẹ ló ṣe ọ́ báyìí? Ó ti tó, àbúrò mi. Ẹ̀gbọ́n+ rẹ ni. Mọ́kàn kúrò lórí ọ̀ràn yìí.” Lẹ́yìn náà, Támárì lọ ń dá gbé nílé Ábúsálómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀. 21 Nígbà tí Ọba Dáfídì gbọ́ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀, inú bí i gan-an.+ Àmọ́ kò fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa ba Ámínónì ọmọ rẹ̀ nínú jẹ́, torí pé òun ni àkọ́bí rẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. 22 Ábúsálómù kò bá Ámínónì sọ nǹkan kan, ì báà jẹ́ búburú tàbí rere; nítorí Ábúsálómù kórìíra+ Ámínónì torí pé ó ti kó ẹ̀gàn bá Támárì+ àbúrò rẹ̀.
23 Lẹ́yìn ọdún méjì gbáko, àwọn tó ń bá Ábúsálómù rẹ́ irun àgùntàn wà ní Baali-hásórì nítòsí Éfúrémù,+ Ábúsálómù sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba.+ 24 Nítorí náà, Ábúsálómù wọlé wá bá ọba, ó sọ́ pé: “Ìránṣẹ́ rẹ ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀. Kí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jọ̀wọ́ bá mi lọ.” 25 Àmọ́ ọba sọ fún Ábúsálómù pé: “Rárá, ọmọ mi. Tí gbogbo wa bá lọ, ìnira la máa jẹ́ fún ọ.” Ábúsálómù ń rọ̀ ọ́ títí, àmọ́ kò gbà láti lọ, kàkà bẹ́ẹ̀ ó súre fún un. 26 Ábúsálómù wá sọ pé: “Tí o kò bá ní lọ, jọ̀wọ́ jẹ́ kí Ámínónì ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.”+ Ọba fún un lésì pé: “Kí ló dé tí á fi bá ọ lọ?” 27 Ṣùgbọ́n Ábúsálómù rọ ọba, torí náà, ó ní kí Ámínónì àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ.
28 Lẹ́yìn náà, Ábúsálómù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ Ámínónì, nígbà tí wáìnì bá ti ń mú inú rẹ̀ dùn, màá sọ fún yín pé, ‘Ẹ ṣá Ámínónì balẹ̀!’ Nígbà náà, kí ẹ pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣebí èmi ni mo pàṣẹ fún yín? Ẹ jẹ́ alágbára, kí ẹ sì ní ìgboyà.” 29 Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù ṣe ohun tí Ábúsálómù pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe sí Ámínónì, ni àwọn ọmọ ọba tó ṣẹ́ kù bá tú ká, kálukú gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* rẹ̀, wọ́n sì sá lọ. 30 Ojú ọ̀nà ni wọ́n ṣì wà tí ìròyìn ti dé ọ̀dọ̀ Dáfídì pé: “Ábúsálómù ti pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó ṣẹ́ kù.” 31 Ni ọba bá dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sùn sílẹ̀, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ náà dúró síbẹ̀, wọ́n fa ẹ̀wù tiwọn náà ya.
32 Àmọ́, Jèhónádábù+ ọmọ Ṣímẹ́à+ tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Dáfídì, sọ pé: “Kí olúwa mi má rò pé gbogbo àwọn ọmọkùnrin ọba ni wọ́n ti pa, nítorí Ámínónì nìkan ló kú.+ Ábúsálómù ló pa àṣẹ yìí, ó sì ti pinnu láti ṣe nǹkan yìí+ látọjọ́ tí Ámínónì ti kó ẹ̀gàn bá Támárì+ àbúrò rẹ̀.+ 33 Ní báyìí, kí olúwa mi ọba má fiyè* sí ìròyìn tí wọ́n sọ pé, ‘Gbogbo àwọn ọmọ ọba ló ti kú’; Ámínónì nìkan ló kú.”
34 Lákòókò yìí, Ábúsálómù ti sá lọ.+ Nígbà tó yá, olùṣọ́ gbójú sókè, ó sì rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń bọ̀ lójú ọ̀nà lẹ́yìn rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè. 35 Ni Jèhónádábù+ bá sọ fún ọba pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ ọba ti dé. Bí ìránṣẹ́ rẹ ṣe sọ ni ó rí.” 36 Bí ó ṣe parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ ọba wọlé, wọ́n ń sunkún kíkankíkan; bákan náà, ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sunkún gidigidi. 37 Àmọ́ Ábúsálómù sá, ó lọ sọ́dọ̀ Tálímáì+ ọmọ Ámíhúdù ọba Géṣúrì. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni Dáfídì fi ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀. 38 Lẹ́yìn tí Ábúsálómù ti sá, ó lọ sí Géṣúrì,+ ó lo ọdún mẹ́ta níbẹ̀.
39 Níkẹyìn, ó ń wu Ọba Dáfídì pé kó lọ sọ́dọ̀ Ábúsálómù, torí pé kò banú jẹ́ mọ́* lórí ikú Ámínónì.
14 Nígbà náà, Jóábù ọmọ Seruáyà+ rí i pé ọkàn ọba ti ń fà sí Ábúsálómù.+ 2 Torí náà, Jóábù ránṣẹ́ sí ìlú Tékóà,+ ó pe ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, ṣe bíi pé ò ń ṣọ̀fọ̀, kí o wọ aṣọ ọ̀fọ̀, má sì fi òróró para.+ Kí o ṣe bí obìnrin tó ti pẹ́ tó ti ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tó kú. 3 Lẹ́yìn náà, kí o wọlé lọ bá ọba, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un.” Ọ̀nà yẹn ni Jóábù gbà fi ọ̀rọ̀ sí obìnrin náà lẹ́nu.*
4 Obìnrin ará Tékóà náà wọlé lọ bá ọba, ó wólẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì sọ pé: “Ọba, ràn mí lọ́wọ́!” 5 Ọba fèsì pé: “Kí ló ṣẹlẹ̀?” Ló bá sọ pé: “Áà, opó ni mí; ọkọ mi ti kú. 6 Èmi ìránṣẹ́ rẹ ní ọmọkùnrin méjì, àwọn méjèèjì bá ara wọn jà ní pápá. Kò sí ẹni tó máa là wọ́n, ni ọ̀kan bá mú èkejì balẹ̀, ó sì pa á. 7 Ní báyìí, gbogbo ìdílé ti dìde sí èmi ìránṣẹ́ rẹ, wọ́n sì ń sọ pé, ‘Fi ẹni tó pa arákùnrin rẹ̀ lé wa lọ́wọ́, kí a lè pa á nítorí ẹ̀mí* arákùnrin rẹ̀ tí ó gbà,+ ì báà tiẹ̀ jẹ́ ajogún, ńṣe la máa pa á!’ Wọ́n fẹ́ pa ọmọ mi kan ṣoṣo tó kù mí kù bí ẹni pa ẹyin iná, kí orúkọ ọkọ mi lè pa rẹ́, kó má sì sí ẹnì kankan tó ṣẹ́ kù* fún un lórí ilẹ̀.”
8 Ọba wá sọ fún obìnrin náà pé: “Máa lọ sí ilé rẹ, màá pàṣẹ pé kí a bójú tó ọ̀rọ̀ rẹ.” 9 Ni obìnrin ará Tékóà náà bá sọ fún ọba pé: “Olúwa mi ọba, kí ẹ̀bi náà wà lórí mi àti lórí ilé bàbá mi, àmọ́ kí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìṣẹ̀.” 10 Ọba wá sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá tún bá ọ sọ nǹkan kan, kí o mú un wá sọ́dọ̀ mi, kò sì ní dààmú rẹ mọ́.” 11 Àmọ́, ó sọ pé: “Jọ̀wọ́ ọba, rántí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀+ má bàa wá, kí ó sì pa mí lọ́mọ.” Ó fèsì pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè,+ ìkankan nínú irun orí ọmọ rẹ kò ní bọ́ sílẹ̀.” 12 Obìnrin náà wá sọ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ sọ ọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi ọba.” Nítorí náà, ọba sọ pé: “Sọ ọ́!”
13 Obìnrin náà bá sọ pé: “Kí wá nìdí tí o fi gbèrò láti ṣe irú nǹkan yìí sí àwọn èèyàn Ọlọ́run?+ Nítorí o ti lé ọmọ rẹ kúrò láwùjọ,+ o kọ̀, o ò mú un pa dà, ohun tí o sọ yìí sì ti fi hàn pé ìwọ náà jẹ̀bi. 14 Ó dájú pé a ó kú, a ó sì dà bí omi tí ó dà sílẹ̀, tí kò ṣeé kó jọ. Àmọ́ Ọlọ́run kì í fẹ́ kí ẹ̀mí* kankan bọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń ronú nípa ìdí tí ẹni tí a lé kúrò láwùjọ fi yẹ kó pa dà sọ́dọ̀ òun. 15 Mo wọlé wá kí n lè sọ ọ̀rọ̀ yìí fún olúwa mi ọba torí pé àwọn èèyàn dẹ́rù bà mí. Nítorí náà, ìránṣẹ́ rẹ sọ pé, ‘Á dáa kí n bá ọba sọ̀rọ̀. Bóyá ọba máa ṣe ohun tí ẹrú rẹ̀ béèrè. 16 Kí ọba fetí sílẹ̀, kí ó sì gba ẹrú rẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tó ń wá ọ̀nà láti pa èmi àti ọmọ mi kan ṣoṣo kúrò lórí ogún tí Ọlọ́run fún wa.’+ 17 Nígbà náà, ìránṣẹ́ rẹ sọ pé, ‘Kí ọ̀rọ̀ olúwa mi ọba tù mí lára,’ nítorí olúwa mi ọba dà bí áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́ tí ó mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì wà pẹ̀lú rẹ.”
18 Ọba wá dá obìnrin náà lóhùn pé: “Jọ̀wọ́, má fi ohunkóhun pa mọ́ fún mi nínú ohun tí mo bá béèrè lọ́wọ́ rẹ.” Obìnrin náà fèsì pé: “Olúwa mi ọba, jọ̀wọ́ béèrè.” 19 Nígbà náà, ọba béèrè pé: “Ṣé Jóábù ló ní kí o ṣe gbogbo ohun tí o ṣe yìí?”+ Obìnrin náà dáhùn pé: “Bí o* ti wà láàyè, olúwa mi ọba, bí olúwa mi ọba ṣe sọ ló rí,* nítorí ìránṣẹ́ rẹ Jóábù ló pàṣẹ fún mi, òun ló sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sí ìránṣẹ́ rẹ lẹ́nu. 20 Ìránṣẹ́ rẹ Jóábù fẹ́ kí ọ̀ràn náà lójú ni ó fi ṣe gbogbo ohun tí ó ṣe yìí, àmọ́ olúwa mi ní ọgbọ́n bíi ti áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́, ó sì mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ yìí.”
21 Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Jóábù pé: “Ó dáa, màá ṣe ohun tí o fẹ́ kí n ṣe.+ Lọ mú ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù+ pa dà wá.” 22 Ni Jóábù bá dojú bolẹ̀, ó dọ̀bálẹ̀, ó sì yin ọba. Jóábù sọ pé: “Lónìí, èmi ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé mo ti rí ojú rere rẹ, olúwa mi ọba, nítorí ọba ti ṣe ohun tí ìránṣẹ́ rẹ̀ béèrè.” 23 Ìgbà náà ni Jóábù gbéra, ó lọ sí Géṣúrì,+ ó sì mú Ábúsálómù wá sí Jerúsálẹ́mù. 24 Àmọ́ ọba sọ pé: “Ilé rẹ̀ ni kí ó pa dà sí, kò gbọ́dọ̀ fojú kàn mí.” Torí náà, Ábúsálómù pa dà sí ilé rẹ̀, kò sì fojú kan ọba.
25 Ní gbogbo Ísírẹ́lì, kò sí arẹwà ọkùnrin tí àwọn èèyàn yìn tó Ábúsálómù. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀, kò sí àbùkù kankan lára rẹ̀. 26 Nígbà tí ó bá gé irun orí rẹ̀, ìwọ̀n irun náà jẹ́ igba (200) ṣékélì* ní ìwọ̀n òkúta* ọba. Ọdọọdún ni ó máa ń gé irun rẹ̀ torí ó máa ń wúwo jù fún un. 27 Ábúsálómù bí ọmọkùnrin mẹ́ta+ àti ọmọbìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Támárì. Obìnrin tó lẹ́wà gan-an ni.
28 Ọdún méjì gbáko ni Ábúsálómù fi gbé ní Jerúsálẹ́mù, síbẹ̀ kò fojú kan ọba.+ 29 Nítorí náà, Ábúsálómù ránṣẹ́ pe Jóábù kí ó lè rán an sí ọba, ṣùgbọ́n Jóábù kò wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó tún ránṣẹ́ sí i nígbà kejì, síbẹ̀ kò wá. 30 Níkẹyìn, ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Oko Jóábù wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tèmi, ó sì ní ọkà bálì níbẹ̀. Ẹ lọ sọ iná sí i.” Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù sọ iná sí oko náà. 31 Jóábù bá gbéra, ó wá bá Ábúsálómù nílé rẹ̀, ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ fi sọ iná sí oko mi?” 32 Ábúsálómù dá Jóábù lóhùn pé: “Wò ó! Mo ránṣẹ́ sí ọ pé, ‘Wá, kí o lè lọ bá mi béèrè lọ́wọ́ ọba pé: “Kí nìdí tí mo fi wá láti Géṣúrì?+ Ì bá dára kí n kúkú dúró síbẹ̀. Ní báyìí, jẹ́ kí n fojú kan ọba, tí mo bá sì jẹ̀bi, kí ó pa mí.”’”
33 Torí náà, Jóábù wọlé lọ bá ọba, ó sì sọ fún un. Lẹ́yìn náà, ó pe Ábúsálómù, Ábúsálómù sì wọlé wá bá ọba, ó dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú ọba. Ọba sì fẹnu ko Ábúsálómù lẹ́nu.+
15 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan yìí, Ábúsálómù ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún ara rẹ̀, ó kó àwọn ẹṣin jọ pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin tí á máa sáré níwájú rẹ̀.+ 2 Ábúsálómù máa ń dìde láàárọ̀ kùtù, á sì dúró sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tó lọ sí ẹnubodè ìlú.+ Nígbà tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ní ẹjọ́ tó ń gbé bọ̀ lọ́dọ̀ ọba,+ Ábúsálómù á pè é, á sì sọ pé: “Ìlú wo lo ti wá?” onítọ̀hún á sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ rẹ ti wá.” 3 Ábúsálómù á wá sọ fún un pé: “Wò ó, ẹjọ́ rẹ dára, ó sì tọ́, àmọ́ kò sí ẹnì kankan láti ọ̀dọ̀ ọba tó máa fetí sí ọ.” 4 Ábúsálómù á tún sọ pé: “Ká ní wọ́n yàn mí ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí ni! Nígbà náà, gbogbo ẹni tó ní ẹjọ́ tàbí tó ń wá ìdájọ́ á lè wá sọ́dọ̀ mi, màá sì rí i pé mo dá ẹjọ́ rẹ̀ bó ṣe tọ́.”
5 Nígbà tí ẹnì kan bá sún mọ́ Ábúsálómù kí ó lè tẹrí ba fún un, Ábúsálómù á na ọwọ́ rẹ̀, á gbá a mú, á sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.+ 6 Ohun tí Ábúsálómù máa ń ṣe sí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tó gbé ẹjọ́ wá sọ́dọ̀ ọba nìyẹn; torí náà, Ábúsálómù ń dọ́gbọ́n fa ojú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì mọ́ra.*+
7 Nígbà tí ọdún mẹ́rin* parí, Ábúsálómù sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí Hébúrónì,+ kí n lè lọ san ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún Jèhófà. 8 Nítorí ìránṣẹ́ rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ ńlá kan+ nígbà tí mò ń gbé ní Géṣúrì+ ní Síríà pé: ‘Tí Jèhófà bá mú mi pa dà wá sí Jerúsálẹ́mù, màá rúbọ sí* Jèhófà.’” 9 Torí náà, ọba sọ fún un pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.” Ló bá gbéra, ó sì lọ sí Hébúrónì.
10 Ábúsálómù wá rán àwọn amí sí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì pé: “Gbàrà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, kí ẹ kéde pé, ‘Ábúsálómù ti di ọba ní Hébúrónì!’”+ 11 Nígbà náà, igba (200) ọkùnrin tẹ̀ lé Ábúsálómù lọ láti Jerúsálẹ́mù; ó pè wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé e láìfura, wọn ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. 12 Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí ó rú àwọn ẹbọ náà, Ábúsálómù ránṣẹ́ pe Áhítófẹ́lì+ ará Gílò, agbani-nímọ̀ràn*+ Dáfídì, láti Gílò+ ìlú rẹ̀. Ọ̀tẹ̀ náà ń gbilẹ̀ sí i, àwọn tó sì wà lẹ́yìn Ábúsálómù ń pọ̀ sí i.+
13 Nígbà tó yá, ẹnì kan wá yọ́ ọ̀rọ̀ sọ fún Dáfídì pé: “Ọkàn àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti yí sọ́dọ̀ Ábúsálómù.” 14 Ní kíá, Dáfídì sọ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ dìde, ẹ sì jẹ́ kí a sá lọ,+ nítorí kò sí ìkankan lára wa tó máa bọ́ lọ́wọ́ Ábúsálómù! Ẹ ṣe kíá, kí ó má bàa yára lé wa bá, kí ó mú àjálù bá wa, kí ó sì fi idà pa ìlú yìí!”+ 15 Àwọn ìránṣẹ́ ọba sọ fún ọba pé: “Ohunkóhun tí olúwa wa ọba bá sọ ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ṣe tán láti ṣe.”+ 16 Nítorí náà, ọba jáde, gbogbo agbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀ lé e, àmọ́ ọba ní kí àwọn wáhàrì*+ mẹ́wàá dúró láti máa tọ́jú ilé. 17 Ọba ń bá ìrìn rẹ̀ lọ, gbogbo àwọn èèyàn náà ń tẹ̀ lé e, wọ́n sì dúró ní Bẹti-méhákì.
18 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ kúrò* àti gbogbo àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ àti àwọn ará Gátì,+ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lé e láti Gátì,+ sì ń kọjá bí ọba ti ń yẹ̀ wọ́n wò.* 19 Nígbà náà, ọba sọ fún Ítáì+ ará Gátì pé: “Kí ló dé tí ìwọ náà fi fẹ́ bá wa lọ? Pa dà, kí o sì lọ máa gbé pẹ̀lú ọba tuntun, nítorí àjèjì ni ọ́, ńṣe ni o sì sá kúrò ní ìlú rẹ. 20 Kò tíì pẹ́ tí o dé, ṣé kí n wá sọ pé kí o máa bá wa rìn káàkiri lónìí, láti lọ síbi tí mo bá ń lọ nígbà tí mo bá ń lọ? Pa dà, ìwọ àti àwọn arákùnrin rẹ, kí Jèhófà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́+ hàn sí ọ!” 21 Ṣùgbọ́n Ítáì dá ọba lóhùn pé: “Bí Jèhófà àti olúwa mi ọba ti wà láàyè, ibikíbi tí olúwa mi ọba bá wà, yálà fún ikú tàbí fún ìyè, ibẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ yóò wà!”+ 22 Dáfídì bá sọ fún Ítáì+ pé: “Ó yá sọdá.” Nítorí náà, Ítáì ará Gátì sọdá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin àti àwọn ọmọ tó wà pẹ̀lú rẹ̀.
23 Gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń sunkún kíkankíkan nígbà tí àwọn èèyàn náà ń sọdá, ọba sì dúró sí ẹ̀gbẹ́ Àfonífojì Kídírónì;+ gbogbo àwọn èèyàn náà sì ń sọdá sójú ọ̀nà tó lọ sí aginjù. 24 Sádókù+ wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Léfì+ tí wọ́n ru àpótí+ májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́; wọ́n sì gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́+ kalẹ̀; Ábíátárì+ náà wà níbẹ̀ ní gbogbo àkókò tí àwọn èèyàn náà sọdá láti inú ìlú náà. 25 Ṣùgbọ́n ọba sọ fún Sádókù pé: “Gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ pa dà sínú ìlú.+ Tí Jèhófà bá ṣojú rere sí mi, á mú mi pa dà, á tún jẹ́ kí n rí i àti ibi tó máa ń wà.+ 26 Àmọ́ tí ó bá sọ pé, ‘Inú mi ò dùn sí ọ,’ nígbà náà, kí ó ṣe ohun tí ó bá dára lójú rẹ̀ sí mi.” 27 Ọba wá sọ fún àlùfáà Sádókù pé: “Ṣebí aríran+ ni ọ́? Pa dà sínú ìlú ní àlàáfíà, kí o mú àwọn ọmọ yín méjèèjì dání, Áhímáásì ọmọ rẹ àti Jónátánì+ ọmọ Ábíátárì. 28 Wò ó, màá dúró ní ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò aginjù, títí màá fi rí ẹni tí wàá ní kí ó wá jíṣẹ́ fún mi.”+ 29 Torí náà, Sádókù àti Ábíátárì gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dúró síbẹ̀.
30 Bí Dáfídì ṣe ń gun Òkè* Ólífì,+ ó ń sunkún bí ó ṣe ń gòkè lọ; ó bo orí rẹ̀, ó sì ń rìn lọ láìwọ bàtà. Gbogbo àwọn èèyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ náà bo orí wọn, wọ́n sì ń sunkún bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ. 31 Dáfídì gbọ́ pé: “Áhítófẹ́lì wà lára àwọn tí ó dìtẹ̀+ pẹ̀lú Ábúsálómù.”+ Ni Dáfídì bá sọ pé: “Jèhófà,+ jọ̀wọ́ sọ ìmọ̀ràn* Áhítófẹ́lì di ti òmùgọ̀!”+
32 Nígbà tí Dáfídì dé orí òkè tí àwọn èèyàn ti máa ń forí balẹ̀ fún Ọlọ́run, Húṣáì+ ará Áríkì+ wá pàdé rẹ̀ níbẹ̀, ẹ̀wù rẹ̀ ti ya, iyẹ̀pẹ̀ sì wà lórí rẹ̀. 33 Àmọ́ Dáfídì sọ fún un pé: “Tí o bá bá mi sọdá, wàá di ẹrù sí mi lọ́rùn. 34 Àmọ́ tí o bá pa dà sínú ìlú, tí o sì sọ fún Ábúsálómù pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ ni mí, Ọba. Ìránṣẹ́ bàbá rẹ ni mí tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́,’+ ìgbà náà ni wàá lè bá mi sọ ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì di asán.+ 35 Ṣebí àlùfáà Sádókù àti Ábíátárì wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ? Gbogbo ohun tí o bá gbọ́ ní ilé ọba+ ni kí o sọ fún àlùfáà Sádókù àti Ábíátárì. 36 Wò ó! Àwọn ọmọ wọn méjèèjì wà pẹ̀lú wọn, Áhímáásì+ ọmọ Sádókù àti Jónátánì+ ọmọ Ábíátárì, kí o ní kí wọ́n wá sọ gbogbo ohun tí o bá gbọ́ fún mi.” 37 Nítorí náà, Húṣáì, ọ̀rẹ́* Dáfídì,+ wá sínú ìlú bí Ábúsálómù ṣe ń wọ Jerúsálẹ́mù.
16 Nígbà tí Dáfídì kọjá orí òkè+ náà díẹ̀, Síbà+ ìránṣẹ́ Méfíbóṣétì+ wá pàdé rẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí wọ́n de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́,* igba (200) búrẹ́dì, ọgọ́rùn-ún (100) ìṣù àjàrà gbígbẹ, ọgọ́rùn-ún (100) ìṣù èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn* àti ìṣà* wáìnì ńlá+ kan sì wà lórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà. 2 Ọba wá béèrè lọ́wọ́ Síbà pé: “Kí nìdí tí o fi kó àwọn nǹkan yìí wá?” Síbà dáhùn pé: “Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wà fún agbo ilé ọba láti gùn, búrẹ́dì àti èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn wà fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin láti jẹ, wáìnì sì wà fún àwọn tí ó bá rẹ̀ ní aginjù láti mu.”+ 3 Ọba wá béèrè pé: “Ọmọ* ọ̀gá rẹ ńkọ́?”+ Síbà dá ọba lóhùn pé: “Ó wà ní Jerúsálẹ́mù, nítorí ó sọ pé, ‘Lónìí, ilé Ísírẹ́lì máa dá ìjọba bàbá mi pa dà fún mi.’”+ 4 Ọba wá sọ fún Síbà pé: “Wò ó! Kí gbogbo ohun tó jẹ́ ti Méfíbóṣétì di tìrẹ.”+ Síbà sọ pé: “Mo tẹrí ba níwájú rẹ. Jẹ́ kí n rí ojú rere rẹ, olúwa mi ọba.”+
5 Nígbà tí Ọba Dáfídì dé Báhúrímù, ọkùnrin ará ilé Sọ́ọ̀lù kan tó ń jẹ́ Ṣíméì+ ọmọ Gérà jáde wá, ó sì ń ṣépè bí ó ṣe ń bọ̀.+ 6 Ó ń sọ òkúta lu Dáfídì àti gbogbo ìránṣẹ́ Ọba Dáfídì àti gbogbo àwọn èèyàn náà títí kan àwọn alágbára ọkùnrin tó wà lápá ọ̀tún àti lápá òsì rẹ̀. 7 Bí Ṣíméì ṣe ń ṣépè ló ń sọ pé: “Kúrò níbí, kúrò níbí, ìwọ apààyàn aláìníláárí yìí! 8 Jèhófà ti mú gbogbo ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ilé Sọ́ọ̀lù wá sórí rẹ, ẹni tí o jọba ní ipò rẹ̀, Jèhófà sì ti fi ìjọba náà lé ọwọ́ Ábúsálómù ọmọ rẹ. Ní báyìí, àjálù ti bá ọ torí pé apààyàn ni ọ́!”+
9 Ábíṣáì ọmọ Seruáyà+ bá sọ fún ọba pé: “Kí nìdí tí òkú ajá+ yìí á fi máa ṣépè fún olúwa mi ọba?+ Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ, kí n sì bẹ́ orí rẹ̀ dà nù.”+ 10 Ṣùgbọ́n ọba sọ pé: “Kí ló kàn yín nínú ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ọmọ Seruáyà?+ Ẹ jẹ́ kó máa ṣépè fún mi,+ torí pé Jèhófà ti sọ fún un pé,+ ‘Ṣépè fún Dáfídì!’ Ta ló máa wá sọ pé, ‘Kí nìdí tí o fi ń ṣe báyìí?’” 11 Dáfídì bá sọ fún Ábíṣáì àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ wò ó, ọmọ tèmi, tó ti ara mi wá ń wọ́nà láti gba ẹ̀mí* mi,+ ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ẹni tó wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì!+ Ẹ fi sílẹ̀, kó máa ṣépè fún mi, torí Jèhófà ti sọ fún un pé kó ṣe bẹ́ẹ̀! 12 Bóyá Jèhófà máa rí ìpọ́njú mi,+ tí Jèhófà yóò sì fi ire san án pa dà fún mi dípò èpè tí ó ń ṣẹ́ lé mi lórí lónìí yìí.”+ 13 Torí náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ń lọ lójú ọ̀nà bí Ṣíméì ṣe ń rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, tí ó sì ń lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Dáfídì, ó ń ṣépè,+ ó ń ju òkúta, ó sì ń da iyẹ̀pẹ̀ lù wọ́n.
14 Níkẹyìn, ọba àti gbogbo àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé ibi tí wọ́n ń lọ, ó ti rẹ̀ wọ́n, torí náà wọ́n sinmi.
15 Ní àkókò yìí, Ábúsálómù àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì dé sí Jerúsálẹ́mù, Áhítófẹ́lì+ sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 16 Nígbà tí Húṣáì+ ará Áríkì,+ ọ̀rẹ́* Dáfídì, wọlé wá sọ́dọ̀ Ábúsálómù, Húṣáì sọ fún Ábúsálómù pé: “Kí ẹ̀mí ọba ó gùn o!+ Kí ẹ̀mí ọba ó gùn o!” 17 Ábúsálómù bá sọ fún Húṣáì pé: “Ṣé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí ọ̀rẹ́ rẹ nìyí? Kí ló dé tí o ò fi bá ọ̀rẹ́ rẹ lọ?” 18 Nítorí náà, Húṣáì sọ fún Ábúsálómù pé: “Rárá, ọ̀dọ̀ ẹni tí Jèhófà àti àwọn èèyàn yìí pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yàn ni mo wà. Mi ò sì ní kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 19 Mo tún sọ pé, Ta ni mi ò bá tún sìn tí kì í bá ṣe ọmọ rẹ̀? Bí mo ṣe sin bàbá rẹ ni màá ṣe sìn ọ́.”+
20 Ni Ábúsálómù bá sọ fún Áhítófẹ́lì pé: “Ẹ gbà mí ní ìmọ̀ràn.*+ Kí ni ká ṣe?” 21 Áhítófẹ́lì wá sọ fún Ábúsálómù pé: “Bá àwọn wáhàrì* bàbá rẹ lò pọ̀,+ àwọn tó fi sílẹ̀ pé kí wọ́n máa tọ́jú ilé.*+ Gbogbo Ísírẹ́lì á wá gbọ́ pé o ti sọ ara rẹ di ẹni ìkórìíra lójú bàbá rẹ, ọkàn gbogbo àwọn tó ń tì ọ́ lẹ́yìn á sì balẹ̀.” 22 Nítorí náà, wọ́n pa àgọ́ kan fún Ábúsálómù sórí òrùlé,+ Ábúsálómù sì bá àwọn wáhàrì bàbá rẹ̀ lò pọ̀+ níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì.+
23 Láyé ìgbà yẹn, ńṣe ni wọ́n máa ń wo ìmọ̀ràn tí Áhítófẹ́lì+ bá fúnni bí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ sọ.* Irú ojú yẹn náà sì ni Dáfídì àti Ábúsálómù fi máa ń wo gbogbo ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì.
17 Nígbà náà, Áhítófẹ́lì sọ fún Ábúsálómù pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n yan ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ọkùnrin, kí a sì gbéra láti lépa Dáfídì lálẹ́ òní. 2 Màá yọ sí i nígbà tó bá ti rẹ̀ ẹ́, tí kò sì ní agbára kankan,*+ màá mú kí ẹ̀rù bà á; gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ á sá lọ, màá sì pa ọba nìkan.+ 3 Màá wá kó gbogbo àwọn èèyàn náà pa dà sọ́dọ̀ rẹ. Ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin tí ò ń lépa yìí ló máa sọ bóyá àwọn èèyàn náà máa pa dà sọ́dọ̀ rẹ. Ìgbà náà ni gbogbo àwọn èèyàn náà yóò wà ní àlàáfíà.” 4 Àbá náà dára lójú Ábúsálómù àti gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì.
5 Síbẹ̀, Ábúsálómù sọ pé: “Jọ̀wọ́, pe Húṣáì+ ará Áríkì pẹ̀lú, kí a lè gbọ́ ohun tó máa sọ.” 6 Torí náà, Húṣáì wọlé wá sọ́dọ̀ Ábúsálómù. Ni Ábúsálómù bá sọ fún un pé: “Ìmọ̀ràn tí Áhítófẹ́lì mú wá rèé. Ṣé kí a ṣe ohun tó dámọ̀ràn? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, sọ ohun tí a máa ṣe.” 7 Ni Húṣáì bá sọ fún Ábúsálómù pé: “Ohun tí Áhítófẹ́lì dámọ̀ràn kò dára lọ́tẹ̀ yìí!”+
8 Húṣáì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ìwọ náà mọ̀ dáadáa pé akíkanjú ni bàbá rẹ àti àwọn ọkùnrin rẹ̀,+ kò sí ohun tí wọn ò lè ṣe,* wọ́n dà bíi bíárì tí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ nù ní pápá.+ Yàtọ̀ síyẹn, jagunjagun ni bàbá rẹ,+ kò ní sùn mọ́jú lọ́dọ̀ àwọn èèyàn náà. 9 Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, inú ihò àpáta* tàbí àwọn ibòmíì ló máa fara pa mọ́ sí;+ tó bá jẹ́ pé òun ló kọ́kọ́ gbéjà kò wá, àwọn tó bá gbọ́ á sọ pé, ‘Wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn tó ń tẹ̀ lé Ábúsálómù!’ 10 Kódà ẹ̀rù á ba ọkùnrin tó láyà bíi kìnnìún,+ ọkàn rẹ̀ á sì domi, torí gbogbo Ísírẹ́lì ló mọ̀ pé akíkanjú ni bàbá rẹ+ àti pé àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní ìgboyà. 11 Ìmọ̀ràn mi ni pé: Jẹ́ kí a kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ rẹ, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà,+ kí wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etíkun,+ kí o sì kó wọn lọ láti jà. 12 Ibikíbi tí a bá ti rí i la ti máa bá a jà, a ó sì ya bò ó bí ìrì ṣe máa ń sẹ̀ sórí ilẹ̀; ẹyọ kan lára wọn ò ní ṣẹ́ kù, àtòun àti àwọn ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 13 Tí ó bá sá sínú ìlú kan, àwa àti gbogbo Ísírẹ́lì á yọ okùn ti ìlú náà, a ó sì wọ́ ọ lọ sínú òkun, tí ò fi ní ku ẹyọ òkúta kan níbẹ̀.”
14 Nígbà náà, Ábúsálómù àti gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ pé: “Ìmọ̀ràn Húṣáì ará Áríkì dára ju+ ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì!” Nítorí Jèhófà ti pinnu* láti sọ ìmọ̀ràn rere Áhítófẹ́lì+ di asán, kí Jèhófà lè mú àjálù bá Ábúsálómù.+
15 Lẹ́yìn náà, Húṣáì sọ fún àlùfáà Sádókù àti Ábíátárì+ pé: “Ohun tí Áhítófẹ́lì dámọ̀ràn fún Ábúsálómù àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì nìyí, ohun tí mo sì dámọ̀ràn nìyí. 16 Ní báyìí, ẹ ránṣẹ́ sí Dáfídì kíákíá, kí ẹ sì kìlọ̀ fún un pé: ‘Má ṣe dúró ní ibi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́* odò* aginjù lálẹ́ òní o, ńṣe ni kí o sọdá, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ọba àti gbogbo àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ni a ó pa rẹ́.’”*+
17 Jónátánì+ àti Áhímáásì+ ń gbé ní Ẹ́ń-rógélì;+ ìránṣẹ́bìnrin kan lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn, àwọn náà sì lọ sọ fún Ọba Dáfídì, nítorí ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ rí wọn pé wọ́n wọnú ìlú. 18 Àmọ́, ọ̀dọ́kùnrin kan rí wọn, ó sì lọ sọ fún Ábúsálómù. Torí náà, àwọn méjèèjì lọ ní kíá, wọ́n sì dé ilé ọkùnrin kan ní Báhúrímù+ tí ó ní kànga ní àgbàlá rẹ̀. Wọ́n sọ̀ kalẹ̀ sínú rẹ̀, 19 ìyàwó ọkùnrin náà da nǹkan bo orí kànga náà, ó sì da ọkà tí wọ́n ti pa sórí rẹ̀, kò sì sẹ́ni tó mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. 20 Àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù wá sọ́dọ̀ obìnrin náà ní ilé rẹ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ibo ni Áhímáásì àti Jónátánì wà?” Obìnrin náà dá wọn lóhùn pé: “Wọ́n gba ibí lọ sọ́nà odò.”+ Ni àwọn ọkùnrin náà bá ń wá wọn kiri, àmọ́ wọn ò rí wọn, torí náà wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù.
21 Lẹ́yìn tí àwọn ọkùnrin náà ti lọ, wọ́n jáde nínú kànga náà, wọ́n sì lọ sọ fún Ọba Dáfídì. Wọ́n sọ fún un pé: “Ẹ gbéra, kí ẹ sì sọdá odò kíákíá, torí ohun tí Áhítófẹ́lì ti dámọ̀ràn láti ṣe sí yín nìyí.”+ 22 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gbéra, wọ́n sì sọdá Jọ́dánì. Nígbà tí ilẹ̀ máa fi mọ́, kò sẹ́ni tó ṣẹ́ kù tí kò tíì sọdá Jọ́dánì.
23 Nígbà tí Áhítófẹ́lì rí i pé wọn ò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn òun, ó de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* ó sì lọ sí ilé rẹ̀ ní ìlú rẹ̀.+ Lẹ́yìn tó ti sọ ohun tí agbo ilé rẹ̀+ máa ṣe, ó pokùn so.*+ Torí náà, ó kú, wọ́n sì sin ín sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba ńlá rẹ̀ sí.
24 Ní àkókò yẹn, Dáfídì lọ sí Máhánáímù,+ Ábúsálómù sì sọdá Jọ́dánì pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì. 25 Ábúsálómù fi Ámásà+ sí ipò Jóábù+ láti máa darí àwọn ọmọ ogun; Ámásà jẹ́ ọmọ ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ítírà, ọmọ Ísírẹ́lì ni Ítírà, òun ló ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Ábígẹ́lì+ ọmọ Náháṣì, arábìnrin Seruáyà, ìyá Jóábù. 26 Gbogbo Ísírẹ́lì àti Ábúsálómù pàgọ́ sí ilẹ̀ Gílíádì.+
27 Gbàrà tí Dáfídì dé Máhánáímù, Ṣóbì ọmọkùnrin Náháṣì láti Rábà+ ti àwọn ọmọ Ámónì àti Mákírù+ ọmọkùnrin Ámíélì láti Lo-débà pẹ̀lú Básíláì+ ọmọ Gílíádì láti Rógélímù 28 kó ibùsùn wá, wọ́n tún kó bàsíà, ìkòkò, àlìkámà,* ọkà bálì, ìyẹ̀fun, àyangbẹ ọkà, ẹ̀wà pàkálà, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì àti ẹ̀gbẹ ọkà wá, 29 wọ́n sì kó oyin, bọ́tà, àgùntàn àti wàrà wá.* Wọ́n kó gbogbo nǹkan yìí wá fún Dáfídì àti àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti jẹ,+ torí wọ́n sọ pé: “Ebi ń pa àwọn èèyàn náà, ó ti rẹ̀ wọ́n, òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n ní aginjù.”+
18 Nígbà náà, Dáfídì ka iye àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì yan àwọn kan ṣe olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún.+ 2 Dáfídì wá fi ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn náà sábẹ́ àṣẹ* Jóábù,+ ó fi ìdá mẹ́ta sábẹ́ àṣẹ Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà,+ ẹ̀gbọ́n Jóábù, ó sì wá fi ìdá mẹ́ta sábẹ́ àṣẹ Ítáì+ ará Gátì. Ọba sọ fún àwọn ọkùnrin náà pé: “Èmi náà á bá yín lọ.” 3 Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “O ò lè lọ o,+ nítorí tí a bá sá, ọ̀rọ̀ wa ò lè jọ wọ́n lójú;* kódà tí ìdajì wa bá kú, kò lè jẹ́ nǹkan kan lójú wọn, nítorí ìwọ nìkan tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) gbogbo wa.+ Torí náà, ó máa dára kí o máa ràn wá lọ́wọ́ látinú ìlú.” 4 Ọba sọ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ bá rí pé ó dára jù ni màá ṣe.” Torí náà, ọba dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè ìlú, gbogbo àwọn èèyàn náà sì jáde lọ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún. 5 Ọba wá pàṣẹ fún Jóábù àti Ábíṣáì àti Ítáì pé: “Ẹ ṣe ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù jẹ́jẹ́ nítorí mi.”+ Gbogbo àwọn ọkùnrin náà gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn olórí nítorí Ábúsálómù.
6 Àwọn ọkùnrin náà lọ sí pápá láti pàdé Ísírẹ́lì, ìjà náà sì wáyé ní igbó Éfúrémù.+ 7 Ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì+ ti ṣẹ́gun àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,+ ọ̀pọ̀ èèyàn sì kú lọ́jọ́ yẹn, ọ̀kẹ́ kan (20,000) èèyàn ló kú. 8 Ogun náà dé gbogbo agbègbè náà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tí igbó kìjikìji pa lọ́jọ́ yẹn pọ̀ ju àwọn tí idà pa lọ.
9 Níkẹyìn, Ábúsálómù ṣàdédé pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* ni Ábúsálómù gùn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* náà sì gba abẹ́ àwọn ẹ̀ka tó díjú lára igi ńlá kan, orí Ábúsálómù há sínú igi ńlá náà, ó rọ̀ dirodiro lókè,* kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* tí ó gùn sì kọjá lọ. 10 Ọkùnrin kan bá rí i, ó sì sọ fún Jóábù+ pé: “Wò ó! Mo rí Ábúsálómù tó so rọ̀ sórí igi ńlá kan.” 11 Jóábù sọ fún ọkùnrin tó wá sọ̀rọ̀ fún un pé: “Ìgbà tí o rí i, kí ló dé tí o ò ṣá a balẹ̀ níbẹ̀? Tayọ̀tayọ̀ ni mi ò bá fi fún ọ ní ẹyọ fàdákà mẹ́wàá àti àmùrè kan.” 12 Àmọ́ ọkùnrin náà sọ fún Jóábù pé: “Kódà, ká ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà ni o fún mi,* mi ò ní gbé ọwọ́ mi sókè sí ọmọ ọba; nítorí a gbọ́ tí ọba pàṣẹ fún ìwọ àti Ábíṣáì pẹ̀lú Ítáì pé, ‘Ẹni yòówù tí ì báà jẹ́, ẹ ṣọ́ra kí ewu kankan má wu ọ̀dọ́kùnrin náà, Ábúsálómù.’+ 13 Ká ní mo ti ṣàìgbọràn ni, tí mo sì gba ẹ̀mí rẹ̀,* ọba kò ní ṣàìmọ̀ nípa rẹ̀, ìwọ náà ò sì ní dáàbò bò mí.” 14 Jóábù bá sọ pé: “Mi ò ní fi àkókò mi ṣòfò lọ́dọ̀ rẹ mọ́!” Torí náà, ó mú aṣóró* mẹ́ta, ó sì fi wọ́n gún ọkàn Ábúsálómù ní àgúnyọ nígbà tí ó ṣì wà láàyè ní àárín igi ńlá náà. 15 Nígbà náà, àwọn ìránṣẹ́ mẹ́wàá tó ń gbé àwọn ohun ìjà Jóábù wá, wọ́n sì kọ lu Ábúsálómù títí ó fi kú.+ 16 Jóábù wá fun ìwo, àwọn ọkùnrin náà sì pa dà lẹ́yìn Ísírẹ́lì tí wọ́n ń lépa; Jóábù ní kí wọ́n dáwọ́ dúró. 17 Wọ́n gbé Ábúsálómù, wọ́n sọ ọ́ sínú kòtò ńlá kan nínú igbó, wọ́n sì kó òkúta lé e lórí pelemọ.+ Gbogbo Ísírẹ́lì sì sá lọ sí ilé wọn.
18 Nígbà tí Ábúsálómù ṣì wà láàyè, ó ṣe òpó kan, ó sì gbé e nàró fún ara rẹ̀ ní Àfonífojì* Ọba,+ torí ó sọ pé: “Mi ò ní ọmọkùnrin tí á máa jẹ́ orúkọ mi lọ.”+ Nítorí náà, ó fi orúkọ ara rẹ̀ pe òpó náà, Ohun Ìrántí Ábúsálómù ni wọ́n sì ń pè é títí di òní yìí.
19 Áhímáásì+ ọmọ Sádókù sọ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n sáré lọ ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọba, nítorí pé Jèhófà ti bá a dá ẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà tó tọ́ bí ó ṣe gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.”+ 20 Àmọ́ Jóábù sọ fún un pé: “Kì í ṣe ìwọ ló máa lọ ròyìn lónìí, o lè lọ ròyìn lọ́jọ́ míì, àmọ́ lónìí, o ò ní lọ ròyìn, nítorí pé ọmọ ọba ló kú.”+ 21 Nígbà náà, Jóábù sọ fún ọmọ Kúṣì+ kan pé: “Lọ sọ ohun tí o rí fún ọba.” Ni ọmọ Kúṣì náà bá tẹrí ba fún Jóábù, ó sì sáré lọ. 22 Áhímáásì ọmọ Sádókù tún sọ fún Jóábù pé: “Ohunkóhun tí ì báà ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n sá tẹ̀ lé ọmọ Kúṣì náà.” Àmọ́, Jóábù sọ pé: “Ọmọ mi, kí nìdí tí o fi fẹ́ sá tẹ̀ lé e, nígbà tí kò sí nǹkan tí o máa ròyìn?” 23 Síbẹ̀, ó ní: “Ohunkóhun tí ì báà ṣẹlẹ̀, jẹ́ kí n sá tẹ̀ lé e.” Nítorí náà, Jóábù sọ fún un pé: “Sá tẹ̀ lé e!” Áhímáásì sì sáré gba agbègbè Jọ́dánì,* níkẹyìn, ó kọjá ọmọ Kúṣì náà.
24 Ní àkókò yìí, Dáfídì jókòó sí àárín ẹnubodè+ méjèèjì tó wà ní ìlú náà, olùṣọ́+ sì lọ sí orí òrùlé ẹnubodè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. Ó gbójú sókè, ó sì rí ọkùnrin kan tí òun nìkan ń sáré bọ̀. 25 Nítorí náà, olùṣọ́ ké sí ọba, ó sì sọ fún un. Ọba sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ òun nìkan ló ń bọ̀, á jẹ́ pé ìròyìn ló mú wá.” Bí ó ṣe ń sún mọ́ tòsí, 26 olùṣọ́ rí ọkùnrin míì tó ń sáré bọ̀. Olùṣọ́ bá pe aṣọ́bodè, ó ní: “Wò ó! Ọkùnrin míì ń dá sáré bọ̀!” Ọba sọ pé: “Ìròyìn ni ẹni yìí náà ń mú bọ̀.” 27 Olùṣọ́ sọ pé: “Mo rí i pé ẹni àkọ́kọ́ ń sáré bí Áhímáásì+ ọmọ Sádókù,” torí náà ọba sọ pé: “Èèyàn rere ni, ìròyìn ayọ̀ ló máa ń mú wá.” 28 Áhímáásì ké sí ọba pé: “Àlàáfíà ni!” Ó tẹrí ba fún ọba, ó sì dojú bolẹ̀. Ó sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó fi àwọn ọkùnrin tí ó dìtẹ̀* sí olúwa mi ọba lé e lọ́wọ́!”+
29 Àmọ́, ọba sọ pé: “Ṣé àlàáfíà ni ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù wà?” Áhímáásì fèsì pé: “Nígbà tí Jóábù rán ìránṣẹ́ ọba àti ìránṣẹ́ rẹ, mo rí i tí ariwo sọ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn, àmọ́ mi ò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀.”+ 30 Nítorí náà, ọba sọ pé: “Bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, dúró síbẹ̀.” Ó bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́, ó sì dúró síbẹ̀.
31 Lẹ́yìn náà, ọmọ Kúṣì dé,+ ó sì sọ pé: “Kí olúwa mi ọba gbọ́ ìròyìn yìí: Jèhófà ti dá ẹjọ́ rẹ lọ́nà tó tọ́ lónìí bí ó ṣe gbà ọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.”+ 32 Ṣùgbọ́n ọba sọ fún ọmọ Kúṣì pé: “Ṣé àlàáfíà ni ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù wà?” Ọmọ Kúṣì fèsì pé: “Kí gbogbo àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba àti gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ dà bí ọ̀dọ́kùnrin náà!”+
33 Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú bá ọba, ó lọ sí yàrá tó wà lórí ẹnubodè, ó sì bú sẹ́kún, bí ó ṣe ń rìn lọ, ó ń sọ pé: “Ọmọ mi Ábúsálómù, ọmọ mi, ọmọ mi Ábúsálómù! Ì bá dáa ká ní èmi ni mo kú dípò rẹ, Ábúsálómù ọmọ mi, ọmọ mi!”+
19 Jóábù gbọ́ ìròyìn pé: “Ọba ń sunkún, ó sì ń ṣọ̀fọ̀ Ábúsálómù.”+ 2 Nítorí náà, ìṣẹ́gun* ọjọ́ yẹn wá di ọ̀fọ̀ fún gbogbo àwọn èèyàn náà, torí wọ́n gbọ́ pé ọba ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀. 3 Àwọn èèyàn náà sì ń yọ́ pa dà sínú ìlú+ ní ọjọ́ yẹn bí àwọn tí ìtìjú bá torí pé wọ́n sá lójú ogun. 4 Ọba bo ojú rẹ̀, ó sì ń sunkún kíkankíkan, ó ní: “Ọmọ mi Ábúsálómù! Ábúsálómù ọmọ mi, ọmọ mi!”+
5 Lẹ́yìn náà, Jóábù lọ bá ọba nínú ilé, ó sọ pé: “O ti kó ìtìjú bá gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ lónìí, àwọn tó gba ẹ̀mí* rẹ sílẹ̀, tí wọ́n tún gba ẹ̀mí* àwọn ọmọkùnrin+ rẹ àti àwọn ọmọbìnrin+ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti àwọn wáhàrì*+ rẹ sílẹ̀ lónìí yìí. 6 O nífẹ̀ẹ́ àwọn tó kórìíra rẹ, o sì kórìíra àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ, nítorí o ti jẹ́ kó ṣe kedere lónìí pé àwọn ìjòyè rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ kò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ, torí ó dá mi lójú pé ká ní Ábúsálómù wà láàyè lónìí, tí gbogbo àwa yòókù sì kú, á tẹ́ ọ lọ́rùn bẹ́ẹ̀. 7 Ní báyìí, dìde, kí o sì lọ gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ níyànjú,* nítorí mo fi Jèhófà búra pé, tí o kò bá jáde, kò ní sí ẹni tó máa ṣẹ́ kù sọ́dọ̀ rẹ lálẹ́ òní. Èyí á burú ju gbogbo jàǹbá tó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ láti ìgbà èwe rẹ títí di báyìí.” 8 Torí náà, ọba dìde, ó sì jókòó sí ẹnubodè, wọ́n ròyìn fún gbogbo àwọn èèyàn pé: “Ọba ti jókòó sí ẹnubodè o.” Ìgbà náà ni gbogbo àwọn èèyàn náà wá síwájú ọba.
Àmọ́ gbogbo Ísírẹ́lì ti fẹsẹ̀ fẹ, kálukú sì ti lọ sí ilé rẹ̀.+ 9 Gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ń ṣe awuyewuye, wọ́n sọ pé: “Ọba ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá+ wa, ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn Filísínì; àmọ́ ní báyìí, ó ti sá kúrò ní ilẹ̀ yìí nítorí Ábúsálómù.+ 10 Ábúsálómù tí a sì fòróró yàn lórí wa+ ti kú lójú ogun.+ Ní báyìí, kí ló dé tí ẹ kò fi ṣe nǹkan kan láti mú ọba pa dà wá?”
11 Ọba Dáfídì ránṣẹ́ sí àlùfáà Sádókù+ àti Ábíátárì+ pé: “Ẹ bá àwọn àgbààgbà Júdà+ sọ̀rọ̀, ẹ sọ fún wọn pé, ‘Kí ló dé tó fi jẹ́ pé ẹ̀yin lẹ máa kẹ́yìn láti mú ọba pa dà sí ilé rẹ̀, nígbà tí ọ̀rọ̀ gbogbo Ísírẹ́lì ti dé ọ̀dọ̀ ọba níbi tó ń gbé? 12 Arákùnrin mi ni yín; ẹ̀jẹ̀* kan náà ni wá. Nítorí náà, kí ló dé tó fi jẹ́ pé ẹ̀yin lẹ máa kẹ́yìn láti mú ọba pa dà wá?’ 13 Kí ẹ sọ fún Ámásà+ pé, ‘Ṣebí ẹ̀jẹ̀* mi ni ọ́? Torí náà, kí Ọlọ́run fìyà jẹ mí gan-an tí o kò bá ní di olórí ọmọ ogun mi láti òní lọ dípò Jóábù.’”+
14 Torí náà, ó yí gbogbo ọkùnrin Júdà lọ́kàn pa dà* bíi pé ẹnì kan ṣoṣo ni wọ́n, wọ́n sì ránṣẹ́ sí ọba pé: “Pa dà wá, ìwọ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.”
15 Nígbà tí Ọba ń pa dà bọ̀, ó dé Jọ́dánì, àwọn èèyàn Júdà sì wá sí Gílígálì+ láti pàdé ọba, kí wọ́n lè mú un sọdá Jọ́dánì. 16 Ìgbà náà ni Ṣíméì+ ọmọ Gérà láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, tó wá láti Báhúrímù sáré wá, òun àti àwọn ọkùnrin Júdà láti pàdé Ọba Dáfídì, 17 ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin láti Bẹ́ńjámínì sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Bákan náà, Síbà+ ẹmẹ̀wà* ilé Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) pẹ̀lú ogún (20) ìránṣẹ́ sáré wá sí Jọ́dánì, wọ́n sì dé ibẹ̀ ṣáájú ọba. 18 Ó* sọdá ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò láti mú agbo ilé ọba sọdá, kí ó sì lè ṣe ohunkóhun tí ọba bá fẹ́. Ṣíméì ọmọ Gérà wólẹ̀ níwájú ọba nígbà tí ó fẹ́ sọdá Jọ́dánì. 19 Ó sọ fún ọba pé: “Kí olúwa mi má ka ẹ̀sùn sí mi lọ́rùn, má sì rántí àìtọ́ tí ìránṣẹ́ rẹ ṣe+ ní ọjọ́ tí olúwa mi ọba jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Kí ọba má ṣe fọkàn sí i, 20 torí ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ dáadáa pé mo ti ṣẹ̀; ìdí nìyẹn tí mo fi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ nínú gbogbo ilé Jósẹ́fù láti wá pàdé olúwa mi ọba.”
21 Ní kíá, Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà+ sọ pé: “Ṣé kò yẹ kí a pa Ṣíméì nítorí nǹkan tó ṣe, torí ó gbé ẹni àmì òróró Jèhófà+ ṣépè?” 22 Àmọ́ Dáfídì sọ pé: “Kí ló kàn yín nínú ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ọmọ Seruáyà,+ tí ẹ fi fẹ́ ta kò mí lónìí? Ṣé ó yẹ kí a pa ẹnikẹ́ni ní Ísírẹ́lì lónìí? Ṣé mi ò mọ̀ pé mo ti pa dà di ọba lórí Ísírẹ́lì lónìí?” 23 Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Ṣíméì pé: “O ò ní kú.” Ọba sì búra fún un.+
24 Méfíbóṣétì,+ ọmọ ọmọ Sọ́ọ̀lù, náà wá pàdé ọba. Kò tíì wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, kò gé irun imú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò fọ aṣọ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ọba ti lọ títí di ọjọ́ tó pa dà ní àlàáfíà. 25 Nígbà tó dé sí* Jerúsálẹ́mù láti pàdé ọba, ọba bi í pé: “Kí ló dé tí o ò fi bá mi lọ, Méfíbóṣétì?” 26 Ó fèsì pé: “Olúwa mi ọba, ìránṣẹ́ mi+ ló tàn mí. Nítorí ìránṣẹ́ rẹ sọ pé, ‘Jẹ́ kí n di ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi,* kí n lè gùn ún, kí n sì bá ọba lọ,’ nítorí arọ+ ni ìránṣẹ́ rẹ. 27 Àmọ́, ó sọ̀rọ̀ èmi ìránṣẹ́ rẹ láìdáa fún ọba.+ Ṣùgbọ́n olúwa mi ọba dà bí áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́, torí náà, ohun tó bá dára lójú rẹ ni kí o ṣe. 28 Gbogbo agbo ilé bàbá mi ni olúwa mi ọba ì bá ti pa, síbẹ̀ o ní kí ìránṣẹ́ rẹ wà lára àwọn tó ń jẹun nídìí tábìlì rẹ.+ Nítorí náà, ẹ̀tọ́ wo ni mo ní tí màá tún máa béèrè ohun míì lọ́wọ́ ọba?”
29 Àmọ́ ọba sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi ń sọ̀rọ̀ báyìí? Mo ti pinnu pé kí ìwọ àti Síbà jọ pín oko náà.”+ 30 Méfíbóṣétì bá sọ fún ọba pé: “Jẹ́ kí ó máa mú gbogbo rẹ̀, ní báyìí tí olúwa mi ọba ti dé ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.”
31 Ìgbà náà ni Básíláì+ ọmọ Gílíádì wá láti Rógélímù sí Jọ́dánì, kí ó lè sin ọba dé Jọ́dánì. 32 Básíláì ti darúgbó gan-an, ẹni ọgọ́rin (80) ọdún ni, ó pèsè oúnjẹ fún ọba nígbà tó ń gbé ní Máhánáímù,+ torí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. 33 Nítorí náà, ọba sọ fún Básíláì pé: “Bá mi sọdá, màá sì pèsè oúnjẹ fún ọ ní Jerúsálẹ́mù.”+ 34 Àmọ́ Básíláì sọ fún ọba pé: “Ọjọ́* mélòó ló kù tí màá lò láyé tí màá fi bá ọba lọ sí Jerúsálẹ́mù? 35 Ẹni ọgọ́rin (80) ọdún ni mí lónìí.+ Ṣé mo ṣì lè fi òye mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú? Ṣé èmi ìránṣẹ́ rẹ lè mọ adùn ohun tí mò ń jẹ àti ohun tí mò ń mu? Ṣé mo ṣì lè gbọ́ ohùn àwọn akọrin + lọ́kùnrin àti lóbìnrin? Ṣé ó wá yẹ kí ìránṣẹ́ rẹ tún jẹ́ ẹrù fún olúwa mi ọba? 36 Tí ìránṣẹ́ rẹ bá lè sin ọba dé Jọ́dánì, ìyẹn náà tó. O ò ní láti san mí lẹ́san kankan. 37 Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ pa dà, jẹ́ kí n kú sí ìlú mi nítòsí ibi tí wọ́n sin bàbá àti ìyá mi + sí. Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ Kímúhámù + rèé. Jẹ́ kí ó bá olúwa mi ọba sọdá, kí o sì ṣe ohun tí ó bá dára lójú rẹ fún un.”
38 Torí náà, ọba sọ pé: “Kímúhámù máa bá mi sọdá, màá sì ṣe ohun tí ó bá dára lójú rẹ fún un; ohunkóhun tí o bá béèrè lọ́wọ́ mi ni màá ṣe fún ọ.” 39 Gbogbo àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọdá Jọ́dánì, nígbà tí ọba sọdá, ọba fi ẹnu ko Básíláì lẹ́nu,+ ó sì súre fún un. Lẹ́yìn náà, Básíláì pa dà sílé. 40 Nígbà tí ọba sọdá sí Gílígálì,+ Kímúhámù bá a sọdá. Gbogbo àwọn èèyàn Júdà àti ìdajì àwọn èèyàn Ísírẹ́lì mú ọba sọdá.+
41 Ìgbà náà ni gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí àwọn arákùnrin wa, àwọn ọkùnrin Júdà fi jí ọ gbé, tí wọ́n sì mú ọba àti agbo ilé rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin Dáfídì+ sọdá Jọ́dánì?” 42 Gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà dá àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì lóhùn pé: “Nítorí pé ìbátan wa+ ni ọba. Kí ló wá ń bí yín nínú lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé a jẹ oúnjẹ kankan sí ọba lọ́rùn ni, àbí ṣé ó fún wa lẹ́bùn ni?”
43 Síbẹ̀, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì dá àwọn ọkùnrin Júdà lóhùn pé: “Àwa ní apá mẹ́wàá nínú ìjọba, torí náà ẹ̀tọ́ tí a ní nínú Dáfídì ju tiyín lọ. Kí ló wá dé tí ẹ kò fi kà wá sí? Ṣé kì í ṣe àwa ló yẹ kó kọ́kọ́ mú ọba wa pa dà ni?” Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Júdà borí* ti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì.
20 Ọkùnrin oníwàhálà kan wà tó ń jẹ́ Ṣébà,+ ọmọ Bíkíráì láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni. Ó fun ìwo,+ ó sì sọ pé: “Àwa kò ní ìpín kankan nínú Dáfídì, a kò sì ní ogún kankan nínú ọmọ Jésè.+ Ìwọ Ísírẹ́lì! Kí kálukú pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run* rẹ̀.”+ 2 Ni gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì bá pa dà lẹ́yìn Dáfídì kí wọ́n lè tẹ̀ lé Ṣébà ọmọ Bíkíráì;+ ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Júdà dúró ti ọba wọn láti Jọ́dánì títí dé Jerúsálẹ́mù.+
3 Nígbà tí Dáfídì dé ilé* rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù,+ ọba mú àwọn wáhàrì* mẹ́wàá tó fi sílẹ̀ láti máa tọ́jú ilé,+ ó sì fi wọ́n sínú ilé tó ní ẹ̀ṣọ́. Ó ń fún wọn ní oúnjẹ àmọ́ kò bá wọn lò pọ̀.+ Inú àhámọ́ ni wọ́n wà títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n ń gbé bíi pé opó ni wọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ wọn ṣì wà láàyè.
4 Ọba wá sọ fún Ámásà+ pé: “Pe àwọn ọkùnrin Júdà jọ fún mi láàárín ọjọ́ mẹ́ta, kí ìwọ náà sì wà níbí.” 5 Torí náà, Ámásà lọ pe Júdà jọ, àmọ́ àkókò tí wọ́n dá fún un kọjá kí ó tó dé. 6 Nígbà náà, Dáfídì sọ fún Ábíṣáì+ pé: “Aburú tí Ṣébà+ ọmọ Bíkíráì máa ṣe fún wa máa ju ti Ábúsálómù lọ.+ Mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má bàa wọnú àwọn ìlú olódi, kí ó sì sá mọ́ wa lọ́wọ́.” 7 Torí náà, àwọn ọkùnrin Jóábù+ àti àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ pẹ̀lú gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin tẹ̀ lé e; wọ́n sì jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù láti lépa Ṣébà ọmọ Bíkíráì. 8 Nígbà tí wọ́n dé tòsí òkúta ńlá tó wà ní Gíbíónì,+ Ámásà+ wá pàdé wọn. Lásìkò yìí, aṣọ ogun ni Jóábù wọ̀, ó sì sán idà kan tó wà nínú àkọ̀ mọ́ ìbàdí rẹ̀. Bí ó ṣe rìn síwájú, idà náà já bọ́.
9 Jóábù sọ fún Ámásà pé: “Arákùnrin mi, ṣé dáadáa lo wà?” Ni Jóábù bá fi ọwọ́ ọ̀tún di irùngbọ̀n Ámásà mú bíi pé ó fẹ́ fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 10 Ámásà kò fura sí idà ọwọ́ Jóábù; Jóábù fi idà náà gún un ní ikùn,+ ìfun rẹ̀ sì tú síta sórí ilẹ̀. Kò gún un lẹ́ẹ̀mejì, ìgbà kan péré ti tó láti pa á. Lẹ́yìn náà, Jóábù àti Ábíṣáì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lépa Ṣébà ọmọ Bíkíráì.
11 Ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin Jóábù dúró sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Kí ẹni tó bá wà lẹ́yìn Jóábù àti ẹni tó bá ń ṣe ti Dáfídì tẹ̀ lé Jóábù!” 12 Ní gbogbo àkókò yìí, Ámásà ń yí nínú ẹ̀jẹ̀ láàárín ọ̀nà. Nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé gbogbo àwọn èèyàn náà ń dúró, ó gbé Ámásà kúrò lójú ọ̀nà, ó sì gbé e lọ sínú igbó. Ó wá fi aṣọ bò ó torí pé gbogbo àwọn tó ń dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ló ń dúró wò ó. 13 Lẹ́yìn tí ó gbé e kúrò lójú ọ̀nà, gbogbo àwọn ọkùnrin náà tẹ̀ lé Jóábù láti lépa Ṣébà+ ọmọ Bíkíráì.
14 Ṣébà gba àárín gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọjá lọ sí Ébẹ́lì ti Bẹti-máákà.+ Àwọn ọmọ Bíkíráì kóra jọ, wọ́n sì tẹ̀ lé e wọnú ìlú.
15 Jóábù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀* dé, wọ́n sì dó tì í ní Ébẹ́lì ti Bẹti-máákà, wọ́n mọ òkìtì ti odi ìlú náà, tí ó fi jẹ́ pé òkìtì yí ìlú náà ká. Gbogbo àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú Jóábù sì ń gbẹ́ ògiri náà lábẹ́, kí wọ́n lè wó o lulẹ̀. 16 Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan láti inú ìlú náà pè, ó ní: “Ẹ tẹ́tí, ẹ gbọ́! Ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ fún Jóábù pé kó máa bọ̀ kí n lè bá a sọ̀rọ̀.” 17 Torí náà, ó sún mọ́ ọn, obìnrin náà sì sọ pé: “Ṣé ìwọ ni Jóábù?” Ó dáhùn pé: “Èmi ni.” Ni ó bá sọ fún un pé: “Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ.” Ó sọ pé: “Mò ń gbọ́.” 18 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n máa ń sọ pé, ‘Ẹ lọ wádìí ní Ébẹ́lì,’ ọ̀ràn náà á sì yanjú. 19 Àwọn tó lẹ́mìí àlàáfíà tí wọ́n sì lóòótọ́ ní Ísírẹ́lì ni mò ń ṣojú fún. Ìlú tó dà bí ìyá ní Ísírẹ́lì lo fẹ́ pa run. Kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ogún Jèhófà+ run?”* 20 Jóábù dáhùn pé: “Kò ṣeé gbọ́ sétí pé mo mú un balẹ̀ tàbí pé mo pa á run. 21 Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ṣébà,+ ọmọ Bíkíráì láti agbègbè olókè Éfúrémù,+ ti dìtẹ̀* sí Ọba Dáfídì. Tí ẹ bá lè fi ọkùnrin yìí nìkan lé mi lọ́wọ́, màá fi ìlú yìí sílẹ̀.” Obìnrin náà bá sọ fún Jóábù pé: “Wò ó! A ó ju orí rẹ̀ sí ọ láti orí ògiri!”
22 Ní kíá, ọlọ́gbọ́n obìnrin náà wọlé lọ bá gbogbo àwọn èèyàn náà, wọ́n gé orí Ṣébà ọmọ Bíkíráì, wọ́n sì jù ú sí Jóábù. Ni ó bá fun ìwo, wọ́n tú ká kúrò ní ìlú náà, kálukú sì lọ sí ilé rẹ̀;+ Jóábù wá pa dà sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọ̀ ọba.
23 Nígbà náà, Jóábù ni olórí gbogbo àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì;+ Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà+ sì jẹ́ olórí àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì.+ 24 Ádórámù+ ni olórí àwọn tí ọba ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun; Jèhóṣáfátì+ ọmọ Áhílúdù sì ni akọ̀wé ìrántí. 25 Ṣéfà ni akọ̀wé; Sádókù+ àti Ábíátárì+ sì ni àlùfáà. 26 Írà ọmọ Jáírì pẹ̀lú sì di olórí àwọn òjíṣẹ́* Dáfídì.
21 Ìyàn+ kan mú nígbà ayé Dáfídì, ọdún mẹ́ta tẹ̀ léra ló sì fi mú. Nítorí náà Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, Jèhófà sì sọ pé: “Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wà lórí Sọ́ọ̀lù àti lórí ilé rẹ̀, nítorí ó pa àwọn ará Gíbíónì.”+ 2 Torí náà, ọba pe àwọn ará Gíbíónì,+ ó sì bá wọn sọ̀rọ̀. (Àwọn ará Gíbíónì kì í ṣe ara àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n jẹ́ àwọn Ámórì+ tó ṣẹ́ kù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti búra pé àwọn máa dá wọn sí,+ àmọ́ Sọ́ọ̀lù wá ọ̀nà títí ó fi pa wọ́n nítorí ìtara tó ní fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Júdà lọ́nà òdì.) 3 Dáfídì sọ fún àwọn ará Gíbíónì pé: “Kí ni kí n ṣe fún yín, ètùtù wo sì ni kí n ṣe, kí ẹ lè súre fún àwọn èèyàn* Jèhófà?” 4 Àwọn ará Gíbíónì sọ fún un pé: “Ọ̀rọ̀ tó wà láàárín àwa àti Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú agbo ilé rẹ̀ kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà;+ bẹ́ẹ̀ ni a kò lè pa ẹnikẹ́ni ní Ísírẹ́lì.” Ni ó bá sọ pé: “Ohunkóhun tí ẹ bá sọ ni màá ṣe fún yín.” 5 Wọ́n sọ fún ọba pé: “Ọkùnrin tí ó pa wá run, tí ó sì gbìmọ̀ láti pa wá rẹ́ kí a má bàa ṣẹ́ kù síbikíbi ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ 6 òun gan-an ni kí o fún wa ní méje lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. A ó sì gbé òkú wọn kọ́*+ níwájú Jèhófà ní Gíbíà+ ti Sọ́ọ̀lù, ẹni tí Jèhófà yàn.”+ Ni Ọba bá sọ pé: “Màá fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”
7 Àmọ́ ṣá, ọba ṣàánú Méfíbóṣétì+ ọmọ Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù nítorí ìbúra tó wáyé níwájú Jèhófà láàárín Dáfídì àti Jónátánì+ ọmọ Sọ́ọ̀lù. 8 Nítorí náà, ọba mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rísípà+ ọmọ Áyà bí fún Sọ́ọ̀lù, ìyẹn, Árímónì àti Méfíbóṣétì, ó tún mú àwọn ọmọkùnrin márààrún tí Míkálì*+ ọmọ Sọ́ọ̀lù bí fún Ádíríélì+ ọmọ Básíláì ará Méhólà. 9 Ó fi wọ́n lé àwọn ará Gíbíónì lọ́wọ́, wọ́n sì gbé òkú wọn kọ́ sórí òkè níwájú Jèhófà.+ Àwọn méjèèje ló kú pa pọ̀, ọjọ́ àkọ́kọ́ ìkórè ni wọ́n pa wọ́n, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì. 10 Lẹ́yìn náà, Rísípà+ ọmọ Áyà mú aṣọ ọ̀fọ̀,* ó sì tẹ́ ẹ sórí àpáta, ó wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè títí òjò fi rọ̀ láti ọ̀run sórí àwọn òkú náà; kò jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn ní ọ̀sán tàbí kí àwọn ẹran inú igbó sún mọ́ wọn ní òru.
11 Wọ́n sọ fún Dáfídì nípa ohun tí Rísípà ọmọ Áyà ṣe, ìyẹn wáhàrì* Sọ́ọ̀lù. 12 Torí náà, Dáfídì lọ kó egungun Sọ́ọ̀lù àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú* Jabeṣi-gílíádì+ tí wọ́n jí egungun náà kó ní ojúde ìlú Bẹti-ṣánì, níbi tí àwọn Filísínì gbé wọn kọ́ sí ní ọjọ́ tí àwọn Filísínì pa Sọ́ọ̀lù ní Gíbóà.+ 13 Ó kó egungun Sọ́ọ̀lù àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ wá láti ibẹ̀, wọ́n tún kó egungun àwọn ọkùnrin tí a ti pa* jọ.+ 14 Lẹ́yìn náà, wọ́n sin egungun Sọ́ọ̀lù àti ti Jónátánì ọmọ rẹ̀ sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì ní Sẹ́là+ ní ibi tí wọ́n sin Kíṣì+ bàbá rẹ̀ sí. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ, Ọlọ́run gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn lórí ilẹ̀ náà.+
15 Lẹ́ẹ̀kan sí i, ogun wáyé láàárín àwọn Filísínì àti Ísírẹ́lì.+ Nítorí náà, Dáfídì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ bá àwọn Filísínì jà, àmọ́ àárẹ̀ mú Dáfídì. 16 Ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù,+ tó ń jẹ́ Iṣibi-bénóbù, tí ìwọ̀n ọ̀kọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ṣékélì*+ bàbà, mú idà tuntun lọ́wọ́, ó fẹ́ ṣá Dáfídì balẹ̀. 17 Ní kíá, Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà wá ràn án lọ́wọ́,+ ó ṣá Filísínì náà balẹ̀, ó sì pa á. Nígbà náà, àwọn ọkùnrin Dáfídì búra fún un pé: “O ò gbọ́dọ̀ bá wa lọ sójú ogun mọ́!+ Má ṣe jẹ́ kí iná Ísírẹ́lì kú!”+
18 Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún bá àwọn Filísínì+ jà ní Góbù. Ìgbà yẹn ni Síbékáì+ ọmọ Húṣà pa Sáfì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù.+
19 Wọ́n tún bá àwọn Filísínì jà+ ní Góbù, Élíhánánì ọmọ Jaare-órégímù ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sì pa Gòláyátì ará Gátì, ẹni tí igi ọ̀kọ̀ rẹ̀ dà bí ọ̀pá àwọn ahunṣọ.*+
20 Ogun tún wáyé ní Gátì, níbi tí ọkùnrin kan wà tí ó tóbi fàkìàfakia, ó ní ìka mẹ́fà-mẹ́fà ní ọwọ́ àti ní ẹsẹ̀, gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìnlélógún (24); òun náà sì wà lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù.+ 21 Ó ń pẹ̀gàn Ísírẹ́lì.+ Torí náà, Jónátánì ọmọ Ṣíméì,+ ẹ̀gbọ́n Dáfídì, pa á.
22 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí jẹ́ àtọmọdọ́mọ Réfáímù ní Gátì, Dáfídì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ló sì pa wọ́n.+
22 Dáfídì kọ ọ̀rọ̀ yìí lórin+ sí Jèhófà ní ọjọ́ tí Jèhófà gbà á lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀+ àti lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù.+ 2 Ó sọ pé:
“Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi ààbò+ mi àti Ẹni tó ń gbà mí sílẹ̀.+
3 Ọlọ́run mi ni àpáta+ mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ààbò,
Apata+ mi àti ìwo* ìgbàlà mi,* ibi ààbò+ mi,*
Àti ibi tí mo lè sá sí,+ olùgbàlà+ mi; ìwọ tí o gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá.
4 Mo ké pe Jèhófà, ẹni tí ìyìn yẹ,
Yóò sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
7 Mo ké pe Jèhófà nínú wàhálà mi,+
Mo sì ń pe Ọlọ́run mi.
Nígbà náà, ó gbọ́ ohùn mi láti tẹ́ńpìlì rẹ̀,
Igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ sì dé etí rẹ̀.+
8 Ayé bẹ̀rẹ̀ sí í mì síwá-sẹ́yìn, ó sì ń mì jìgìjìgì;+
Àwọn ìpìlẹ̀ ọ̀run mì tìtì+
Wọ́n sì ń mì síwá-sẹ́yìn nítorí a ti mú un bínú.+
11 Ó gun kérúbù,+ ó sì ń fò bọ̀.
A rí i lórí ìyẹ́ apá áńgẹ́lì kan.*+
12 Ó wá fi òkùnkùn bò ó bí àgọ́,+
Nínú ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀.
13 Láti inú ìmọ́lẹ̀ tó wà níwájú rẹ̀ ni ẹyin iná ti ń jó.
16 Ìsàlẹ̀ òkun hàn síta;+
Àwọn ìpìlẹ̀ ayé hàn síta nítorí ìbáwí Jèhófà,
Nípa èémí tó tú jáde ní ihò imú rẹ̀.+
17 Ó na ọwọ́ rẹ̀ láti òkè;
Ó mú mi, ó sì fà mí jáde látinú omi jíjìn.+
18 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,+
Lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra mi, tí wọ́n sì lágbára jù mí lọ.
19 Wọ́n kò mí lójú ní ọjọ́ àjálù mi,+
Ṣùgbọ́n Jèhófà ni alátìlẹyìn mi.
22 Nítorí mo ti pa àwọn ọ̀nà Jèhófà mọ́,
Mi ò hùwà burúkú, kí n wá fi Ọlọ́run mi sílẹ̀.
26 Ìwọ jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin;+
Ìwọ ń hùwà àìlẹ́bi sí akíkanjú ọkùnrin aláìlẹ́bi;+
27 Ìwọ jẹ́ mímọ́ sí ẹni tí ó mọ́,+
28 Ò ń gba àwọn ẹni rírẹlẹ̀ là,+
Ṣùgbọ́n o kì í fi ojú rere wo àwọn agbéraga, o sì ń rẹ̀ wọ́n wálẹ̀.+
Apata ló jẹ́ fún gbogbo àwọn tó fi í ṣe ibi ààbò.+
32 Ta ni Ọlọ́run bí kò ṣe Jèhófà?+
Ta sì ni àpáta bí kò ṣe Ọlọ́run wa?+
34 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bíi ti àgbọ̀nrín,
Ó sì mú mi dúró ní àwọn ibi gíga.+
35 Ó ń kọ́ ọwọ́ mi ní ogun,
Apá mi sì lè tẹ ọrun tí a fi bàbà ṣe.
38 Màá lépa àwọn ọ̀tá mi, màá sì pa wọ́n run;
Mi ò ní pa dà títí wọ́n á fi pa rẹ́.
39 Màá pa wọ́n run, màá sì fọ́ wọn túútúú, kí wọ́n má bàa gbérí mọ́;+
Wọ́n á ṣubú sábẹ́ ẹsẹ̀ mi.
42 Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àmọ́ kò sí ẹni tó máa gbà wọ́n;
Kódà, wọ́n ké pe Jèhófà, àmọ́ kò dá wọn lóhùn.+
43 Màá gún wọn kúnná bí eruku ilẹ̀;
Màá lọ̀ wọ́n, màá sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ojú ọ̀nà.
44 Wàá gbà mí lọ́wọ́ àwọn èèyàn mi tó ń wá àléébù.+
45 Àwọn àjèjì á wá ba búrúbúrú níwájú mi;+
Ohun tí wọ́n bá gbọ́ nípa mi á mú kí wọ́n ṣègbọràn sí mi.*
46 Ọkàn àwọn àjèjì á domi;*
Wọ́n á jáde tẹ̀rùtẹ̀rù látinú ibi ààbò wọn.
47 Jèhófà wà láàyè! Ìyìn ni fún Àpáta mi!+
Kí a gbé Ọlọ́run tó jẹ́ àpáta ìgbàlà mi ga.+
48 Ọlọ́run tòótọ́ ń gbẹ̀san fún mi;+
Ó ń ṣẹ́gun àwọn èèyàn lábẹ́ mi;+
49 Ó ń gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
50 Ìdí nìyẹn tí màá fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà, láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+
23 Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ kẹ́yìn nìyí:+
‘Nígbà tí ẹni tó ń ṣàkóso aráyé bá jẹ́ olódodo,+
Tó ń fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣàkóso,+
4 Á dà bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn yọ,+
Tí ojúmọ́ mọ́, tí kò sí ìkùukùu.
Bí ìmọ́lẹ̀ tó yọ lẹ́yìn tí òjò dá,
Tó ń mú kí ewéko yọ láti inú ilẹ̀.’+
5 Ǹjẹ́ kì í ṣe bí ilé mi ṣe rí nìyẹn lójú Ọlọ́run?
Torí ó ti bá mi dá májẹ̀mú ayérayé,+
Tó wà létòlétò, tó sì wà lábẹ́ ààbò.
Nítorí ó jẹ́ ìgbàlà mi látòkèdélẹ̀ àti gbogbo ìdùnnú mi,
Ǹjẹ́ kì í ṣe ìdí tó fi ń mú kó gbilẹ̀+ nìyẹn?
6 Àmọ́ a kó àwọn aláìníláárí dà nù+ bí igi ẹlẹ́gùn-ún,
Nítorí a kò lè fi ọwọ́ mú wọn.
7 Kí ẹnì kan tó lè fọwọ́ kàn wọ́n,
Ó ní láti gbára dì, kí ó ní irin àti ọ̀kọ̀ lọ́wọ́,
Ó sì gbọ́dọ̀ dáná sun wọ́n pátápátá ní ibi tí wọ́n wà.”
8 Orúkọ àwọn jagunjagun Dáfídì tó lákíkanjú+ nìyí: Joṣebi-báṣébétì tó jẹ́ Tákímónì, olórí àwọn mẹ́ta náà.+ Ìgbà kan wà tó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọkùnrin. 9 Ẹni tí ó tẹ̀ lé e ni Élíásárì+ ọmọ Dódò+ ọmọ Áhóhì, ó wà lára àwọn jagunjagun mẹ́ta tó lákíkanjú tó wà pẹ̀lú Dáfídì nígbà tí wọ́n pe àwọn Filísínì níjà. Wọ́n ti kóra jọ láti jagun níbẹ̀, nígbà tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sá pa dà, 10 ó dúró, ó sì ń pa àwọn Filísínì, títí apá fi ń ro ó, tí ọwọ́ rẹ̀ sì gan nítorí idà tó dì mú.+ Torí náà, Jèhófà mú kí ìṣẹ́gun* ńlá wáyé ní ọjọ́ yẹn;+ àwọn èèyàn náà pa dà sẹ́yìn rẹ̀ láti wá bọ́ nǹkan kúrò lára àwọn tí ó ti pa.
11 Ẹni tí ó tẹ̀ lé e sì ni Ṣámà ọmọ Ágéè tó jẹ́ Hárárì. Àwọn Filísínì kóra jọ sí Léhì, sórí ilẹ̀ kan tí ẹ̀wà lẹ́ńtìlì pọ̀ sí; àwọn èèyàn náà sì sá nítorí àwọn Filísínì. 12 Àmọ́ ó dúró ní àárín ilẹ̀ náà, kò jẹ́ kí wọ́n gbà á, ó sì ń pa àwọn Filísínì náà, tó fi jẹ́ pé Jèhófà mú kí ìṣẹ́gun*+ ńlá wáyé.
13 Mẹ́ta lára ọgbọ̀n (30) ọkùnrin tó jẹ́ olórí lọ sọ́dọ̀ Dáfídì lásìkò ìkórè nígbà tó wà nínú ihò àpáta ní Ádúlámù,+ àwùjọ* àwọn Filísínì sì pàgọ́ sí Àfonífojì* Réfáímù.+ 14 Nígbà yẹn, Dáfídì wà ní ibi ààbò,+ àwùjọ ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó sì wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. 15 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ ohun tó ń wù ú, ó ní: “Ì bá dára ká ní mo lè rí omi mu láti inú kòtò omi tó wà ní ẹnubodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù!” 16 Ni àwọn jagunjagun mẹ́ta tó lákíkanjú náà bá fipá wọnú ibùdó àwọn Filísínì, wọ́n fa omi láti inú kòtò omi tó wà ní ẹnubodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọ́n sì gbé e wá fún Dáfídì; àmọ́ ó kọ̀, kò mu ún, ńṣe ló dà á jáde fún Jèhófà.+ 17 Ó sọ pé: “Jèhófà, kò ṣeé gbọ́ sétí pé mo ṣe nǹkan yìí! Ṣé ó yẹ kí n mu ẹ̀jẹ̀+ àwọn ọkùnrin tó fẹ̀mí* ara wọn wewu yìí?” Torí náà, ó kọ̀, kò mu ún. Àwọn ohun tí àwọn jagunjagun rẹ̀ mẹ́ta tó lákíkanjú ṣe nìyẹn.
18 Ábíṣáì+ ẹ̀gbọ́n Jóábù ọmọ Seruáyà+ ni olórí àwọn mẹ́ta míì; ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300), òun náà sì lórúkọ bí àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́.+ 19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ló ta yọ jù láàárín àwọn mẹ́ta kejì, tó sì jẹ́ olórí wọn, kò wọ ẹgbẹ́ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́.
20 Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà jẹ́ akíkanjú ọkùnrin* tó gbé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe ní Kábúséélì.+ Ó pa àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Áríélì ará Móábù bí, ó wọ inú kòtò omi lọ́jọ́ kan tí yìnyín bolẹ̀, ó sì pa kìnnìún.+ 21 Ó tún mú ọkùnrin ará Íjíbítì kan tó tóbi fàkìàfakia balẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kọ̀ wà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà, ó fi ọ̀pá bá a jà, ó já ọ̀kọ̀ náà gbà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ òun fúnra rẹ̀ pa á. 22 Àwọn ohun tí Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà ṣe nìyẹn, ó lórúkọ bí àwọn akíkanjú jagunjagun mẹ́ta náà. 23 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ta yọ ju àwọn ọgbọ̀n (30) náà, kò wọ ẹgbẹ́ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́. Àmọ́ Dáfídì yàn án ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
24 Ásáhélì+ arákùnrin Jóábù wà lára àwọn ọgbọ̀n (30) náà, àwọn ni: Élíhánánì ọmọ Dódò ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ 25 Ṣámà ará Háródù, Élíkà ará Háródù, 26 Hélésì+ tó jẹ́ Pálútì, Írà+ ọmọ Íkéṣì ará Tékóà, 27 Abi-ésérì+ ọmọ Ánátótì,+ Mébúnáì ọmọ Húṣà, 28 Sálímónì ọmọ Áhóhì, Máháráì+ ará Nétófà, 29 Hélébù ọmọ Báánà ará Nétófà, Ítáì ọmọ Ríbáì ará Gíbíà ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, 30 Bẹnáyà+ ará Pírátónì, Hídáì tó wá láti àwọn àfonífojì Gááṣì,+ 31 Abi-álíbónì tó jẹ́ Ábátì, Ásímáfẹ́tì ará Báhúmù, 32 Élíábà tó jẹ́ Ṣáálíbónì, àwọn ọmọ Jáṣénì, Jónátánì, 33 Ṣámà tó jẹ́ Hárárì, Áhíámù ọmọ Ṣárárì tó jẹ́ Hárárì, 34 Élífélétì ọmọ Áhásíbáì ọmọ ará Máákátì, Élíámù ọmọ Áhítófẹ́lì+ ará Gílò, 35 Hésírò ará Kámẹ́lì, Pááráì ará Árábù, 36 Ígálì ọmọ Nátánì ará Sóbà, Bánì ọmọ Gádì, 37 Sélékì ọmọ Ámónì, Náháráì ará Béérótì, tó ń bá Jóábù ọmọ Seruáyà gbé ìhámọ́ra, 38 Írà tó jẹ́ Ítírì, Gárébù tó jẹ́ Ítírì,+ 39 Ùráyà+ ọmọ Hétì, gbogbo wọn jẹ́ mẹ́tàdínlógójì (37).
24 Inú tún bí Jèhófà sí Ísírẹ́lì+ nígbà tí ẹnì kan mú kí Dáfídì* ṣe ohun kan sí wọn, ó ní: “Lọ, ka iye+ àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Júdà.”+ 2 Nítorí náà, ọba sọ fún Jóábù+ olórí àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, lọ yí ká gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà,+ kí ẹ sì forúkọ àwọn èèyàn náà sílẹ̀, kí n lè mọ iye wọn.” 3 Ṣùgbọ́n Jóábù sọ fún ọba pé: “Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ sọ àwọn èèyàn náà di púpọ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100), kí ó sì ṣojú olúwa mi ọba, àmọ́ kí nìdí tí olúwa mi ọba fi fẹ́ ṣe irú nǹkan yìí?”
4 Àmọ́ ọ̀rọ̀ ọba borí ti Jóábù àti ti àwọn olórí ọmọ ogun. Torí náà, Jóábù àti àwọn olórí ọmọ ogun jáde níwájú ọba láti forúkọ àwọn èèyàn Ísírẹ́lì sílẹ̀.+ 5 Wọ́n sọdá Jọ́dánì, wọ́n sì dó sí Áróérì,+ lápá ọ̀tún* ìlú ní àárín àfonífojì, wọ́n forí lé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Gádì, wọ́n sì dé Jásérì.+ 6 Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n lọ sí Gílíádì+ àti ilẹ̀ Tatimu-hódíṣì, wọ́n ń lọ títí dé Dani-jáánì, wọ́n sì lọ yí ká dé Sídónì.+ 7 Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí ibi ààbò Tírè+ àti gbogbo ìlú àwọn Hífì+ àti ti àwọn ọmọ Kénáánì, níkẹyìn wọ́n dé Négébù+ ti Júdà ní Bíá-ṣébà.+ 8 Bí wọ́n ṣe lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà nìyẹn, wọ́n sì wá sí Jerúsálẹ́mù ní òpin oṣù mẹ́sàn-án àti ogún (20) ọjọ́. 9 Jóábù wá fún ọba ní iye àwọn èèyàn tó forúkọ wọn sílẹ̀. Ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) jagunjagun tó ní idà ló wà ní Ísírẹ́lì, àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000).+
10 Àmọ́ ọkàn* Dáfídì dá a lẹ́bi+ lẹ́yìn tó ti ka iye àwọn èèyàn náà. Dáfídì wá sọ fún Jèhófà pé: “Mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀+ ńlá nítorí ohun tí mo ṣe yìí. Ní báyìí, Jèhófà, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì í,+ nítorí mo ti hùwà òmùgọ̀ gan-an.”+ 11 Nígbà tí Dáfídì dìde ní àárọ̀, Jèhófà bá wòlíì Gádì+ tó jẹ́ aríran Dáfídì sọ̀rọ̀, ó ní: 12 “Lọ sọ fún Dáfídì pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ohun mẹ́ta ni màá fi síwájú rẹ. Mú ọ̀kan tí o fẹ́ kí n ṣe sí ọ.”’”+ 13 Torí náà, Gádì wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé kí ìyàn ọdún méje mú ní ilẹ̀ rẹ?+ Tàbí kí o fi oṣù mẹ́ta máa sá fún àwọn ọ̀tá rẹ nígbà tí wọ́n bá ń lépa rẹ?+ Tàbí kí àjàkálẹ̀ àrùn fi ọjọ́ mẹ́ta jà ní ilẹ̀ rẹ?+ Ní báyìí, fara balẹ̀, kí o ro ohun tí o fẹ́ kí n sọ fún Ẹni tó rán mi.” 14 Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Gádì pé: “Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú bá mi gan-an. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí a ṣubú sí ọwọ́ Jèhófà,+ nítorí àánú rẹ̀ pọ̀;+ ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ èèyàn.”+
15 Nígbà náà, Jèhófà rán àjàkálẹ̀ àrùn+ sí Ísírẹ́lì láti àárọ̀ títí di àkókò tó dá, tí ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) fi kú+ lára àwọn èèyàn náà láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà.+ 16 Nígbà tí áńgẹ́lì náà na ọwọ́ rẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù láti pa á run, Jèhófà pèrò dà* lórí àjálù+ náà, ó sì sọ fún áńgẹ́lì tó ń pa àwọn èèyàn náà pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Gbé ọwọ́ rẹ wálẹ̀.” Áńgẹ́lì Jèhófà wà nítòsí ibi ìpakà Áráúnà+ ará Jébúsì.+
17 Nígbà tí Dáfídì rí áńgẹ́lì tó ń pa àwọn èèyàn náà, ó sọ fún Jèhófà pé: “Èmi ni mo ṣẹ̀, èmi ni mo sì ṣe ohun tí kò dáa; àmọ́ kí ni àwọn àgùntàn+ yìí ṣe? Jọ̀ọ́, èmi àti ilé bàbá mi+ ni kí o gbé ọwọ́ rẹ sókè sí.”
18 Torí náà, Gádì wọlé wá bá Dáfídì ní ọjọ́ yẹn, ó sì sọ fún un pé: “Lọ, kí o ṣe pẹpẹ kan fún Jèhófà ní ibi ìpakà Áráúnà ará Jébúsì.”+ 19 Dáfídì wá lọ bí Gádì ṣe sọ, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún un. 20 Nígbà tí Áráúnà wo ìsàlẹ̀, tí ó sì rí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áráúnà jáde wá, ó tẹrí ba fún ọba, ó sì dojú bolẹ̀. 21 Áráúnà béèrè pé: “Kí nìdí tí olúwa mi ọba fi wá sọ́dọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀?” Dáfídì dáhùn pé: “Láti ra ibi ìpakà yìí lọ́wọ́ rẹ ni, kí n lè mọ pẹpẹ kan fún Jèhófà, kí àjàkálẹ̀ àrùn tó ń pa àwọn èèyàn yìí lè dáwọ́ dúró.”+ 22 Ṣùgbọ́n Áráúnà sọ fún Dáfídì pé: “Kí olúwa mi ọba mú un, kó sì fi ohun tó bá rí pé ó dára* rúbọ. Màlúù rèé fún ẹbọ sísun, ohun èlò ìpakà àti igi àjàgà sì rèé fún iná dídá. 23 Gbogbo nǹkan yìí ni èmi Áráúnà fún ọba.” Lẹ́yìn náà, Áráúnà sọ fún ọba pé: “Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣojú rere sí ọ.”
24 Àmọ́ ọba sọ fún Áráúnà pé: “Rárá o, mo gbọ́dọ̀ rà á lọ́wọ́ rẹ ní iye kan. Mi ò ní rú ẹbọ sísun tí kò ná mi ní nǹkan kan sí Jèhófà Ọlọ́run mi.” Ni Dáfídì bá ra ibi ìpakà náà àti màlúù náà ní àádọ́ta (50) ṣékélì fàdákà.*+ 25 Dáfídì mọ pẹpẹ+ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ó sì rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀. Lẹ́yìn náà, Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ilẹ̀ náà,+ àjàkálẹ̀ àrùn tó ń pa àwọn èèyàn Ísírẹ́lì sì dáwọ́ dúró.
Tàbí “pa.”
Tàbí “ẹ̀mí mi kò tíì bọ́.”
Tàbí “dáyádémà.”
Tàbí “ọ̀fọ̀.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “ẹni àrídunnú.”
Ní Héb., “Iye ọjọ́.”
Tàbí “díje.”
Tàbí kó jẹ́, “Bítírónì.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “wò ó! ọwọ́ mi wà pẹ̀lú rẹ.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “nítorí ẹ̀jẹ̀.”
Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ọkùnrin tó yarọ tí wọ́n ní kó máa ṣe iṣẹ́ obìnrin.
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Ní Héb., “Bàbà.”
Ní Héb., “àwọn aláìṣòdodo ọmọ.”
Tàbí “oúnjẹ ọ̀fọ̀.”
Ní Héb., “ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù.”
Ní Héb., “ọwọ́ rẹ̀ rọ.”
Tàbí “jàǹdùkú.”
Tàbí “yarọ.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “tún ọkàn mi rà pa dà.”
Ní Héb., “Egungun àti ara.”
Ní Héb., “ìwọ lò ń mú Ísírẹ́lì jáde tí o sì ń mú un wọlé.”
Tàbí “ọkàn Dáfídì.”
Tàbí kó jẹ́, “ó.”
Tàbí “Mílò.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “iyẹ̀pẹ̀ tí a kó jọ gègèrè.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ó túmọ̀ sí “Ọ̀gá Àwọn Tó Ń Ya Luni.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “láàárín.”
Tàbí “aro.”
Tàbí “inú Dáfídì bà jẹ́.”
Ó túmọ̀ sí “Ìbínú Ru sí Úsà.”
Ní Héb., “sán.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “wíńdò.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “rìn.”
Ní Héb., “ké.”
Tàbí “sọ ìdílé rẹ di ìdílé tó ń jọba.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “ẹni tó máa jáde láti inú rẹ.”
Tàbí kó jẹ́, “Ádámù.”
Tàbí “òfin.”
Tàbí “ohun tó bá ìfẹ́ rẹ mu.”
Tàbí “sọ ìdílé rẹ di ìdílé tó ń jọba.”
Ní Héb., “ọkàn.”
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “pátì.”
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “gba Dáfídì là.”
Tàbí “apata ribiti.”
Tàbí “gba Dáfídì là.”
Ní Héb., “àlùfáà.”
Tàbí “ó yarọ.”
Ní Héb., “jẹ búrẹ́dì.”
Tàbí “àfiyèsí.”
Tàbí “ìránṣẹ́.”
Tàbí kó jẹ́, “mi.”
Tàbí “àwọn ọkùnrin Tóbù.”
Tàbí “àwọn ọkùnrin Tóbù.”
Ní Héb., “sí ọwọ́.”
Ìyẹn, Yúfírétì.
Ìyẹn, nígbà tí ọdún yí po.
Tàbí “Ní ọjọ́rọ̀.”
Tàbí “ààfin.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àìmọ́ ti nǹkan oṣù.
Ní Héb., “wẹ ẹsẹ̀ rẹ.”
Tàbí “ìpín ọba,” ìyẹn, ohun tí ẹni tó gbàlejò fi ránṣẹ́ sí àlejò rẹ̀ pàtàkì.
Tàbí “tí ọkàn rẹ sì wà láàyè.”
Ní Héb., “burú lójú Jèhófà.”
Tàbí “ọmọnìkejì rẹ.”
Ní Héb., “ní ojú oòrùn yìí.”
Ní Héb., “iwájú oòrùn.”
Tàbí “ti jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kọjá lọ.”
Tàbí “ààfin.”
Látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “Àlàáfíà.”
Ó túmọ̀ sí “Àyànfẹ́ Jáà.”
Tàbí “ìlú ìjọba.”
Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ibi tí omi ìlú náà ti ń wá.
Ní Héb., “wọ́n á sì máa fi orúkọ mi pè é.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Ìyẹn, ẹni tí kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí.
Tàbí “oúnjẹ ìtùnú.”
Tàbí “oúnjẹ ìtùnú.”
Tàbí “oúnjẹ ìtùnú.”
Tàbí “Aṣọ tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.
Ní Héb., “fọkàn.”
Tàbí “ó ti gba ìtùnú.”
Tàbí “sọ ohun tó máa sọ fún un.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “yè bọ́.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “kò sẹ́ni tó lè yà sọ́tùn-ún tàbí sósì nínú ohun tí olúwa mi ọba sọ.”
Nǹkan bíi kìlógíráàmù 2.3. Wo Àfikún B14.
Èyí lè jẹ́ ìwọ̀n tí wọ́n gbé sí ààfin ọba tàbí ṣékélì “ọba” kan tó yàtọ̀ sí ṣékélì tí wọ́n sábà máa ń lò.
Ní Héb., “jí ọkàn àwọn èèyàn Ísírẹ́lì.”
Tàbí kó jẹ́, “40 ọdún.”
Tàbí “jọ́sìn.” Ní Héb., “ṣe iṣẹ́ ìsìn fún.”
Tàbí “olùdámọ̀ràn.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “tí wọ́n ń sọdá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.”
Tàbí “sì ń sọdá níwájú ọba.”
Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè.”
Tàbí “àmọ̀ràn.”
Tàbí “ọ̀rẹ́ àfinúhàn.”
Tàbí “tí wọ́n dì ní gàárì.”
Ní pàtàkì, èso ọ̀pọ̀tọ́ àti bóyá èso déètì.
Ó dà bíi jọ́ọ̀gì omi.
Tàbí “ọmọ ọmọ.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọ̀rẹ́ àfinúhàn.”
Tàbí “àmọ̀ràn.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “bí ìgbà tí èèyàn bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́.”
Tàbí “tí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì ti rọ.”
Tàbí “ọkàn wọn korò.”
Tàbí “kòtò; àfonífojì tóóró.”
Tàbí “pàṣẹ.”
Ìyẹn, ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ là kọjá lára odò.
Tàbí kó jẹ́, “aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní.”
Ní Héb., “gbé mì.”
Tàbí “di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì.”
Tàbí “fún ara rẹ̀ lọ́rùn pa.”
Tàbí “wíìtì.”
Ní Héb., “ìkẹ̀tẹ́ wàrà màlúù.”
Ní Héb., “sí ìkáwọ́.”
Ní Héb., “wọn ò lè fọkàn sí wa.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka
Ní Héb., “láàárín ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka
Ní Héb., “Ká ní mo tiẹ̀ ń wọn ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà ní àtẹ́wọ́ mi.”
Tàbí “Ká ní mo ti ṣe àdàkàdekè sí ọkàn rẹ̀ ni.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ “ọ̀kọ̀.” Ní Héb., “ọ̀pá.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “agbègbè náà.”
Ní Héb., “gbé ọwọ́ wọn sókè.”
Tàbí “ìgbàlà.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “sọ ọ̀rọ̀ tó máa wọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ́kàn.”
Ní Héb., “egungun àti ara.”
Ní Héb., “egungun àti ara.”
Ní Héb., “ó tẹ ọkàn gbogbo ọkùnrin Júdà.”
Tàbí “ìránṣẹ́.”
Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n.”
Tàbí kó jẹ́, “wá láti.”
Tàbí “di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì.”
Ní Héb., “Ọjọ́ tó jẹ́ ọdún.”
Tàbí “le ju.”
Tàbí kó jẹ́, “sí àgọ́.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “Wọ́n.”
Ní Héb., “gbé ogún Jèhófà mì.”
Ní Héb., “gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.”
Ní Héb., “àlùfáà.”
Ní Héb., “ogún.”
Ní Héb., “gbé wọn síta,” ìyẹn ni pé wọ́n á dá apá àti ẹsẹ̀ wọn.
Tàbí kó jẹ́, “Mérábù.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí kó jẹ́, “onílẹ̀.”
Ní Héb., “gbé síta.”
Nǹkan bíi kìlógíráàmù 3.42. Wo Àfikún B14.
Tàbí “olófì.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “olùgbàlà mi tó lágbára.”
Tàbí “ibi gíga mi tó láàbò.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ìyẹ́ afẹ́fẹ́.”
Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”
Tàbí “mo jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “ìwọ ń ṣe bí ẹni tí kò gbọ́n sí àwọn oníbékebèke.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Tàbí “ọrùn ẹsẹ̀.”
Tàbí “Wàá jẹ́ kí n gbá ẹ̀yìn ọrùn àwọn ọ̀tá mi mú.”
Ní Héb., “lẹ́nu mọ́.”
Ní Héb., “Tí wọ́n bá gbọ́ ìró mi, wọ́n á ṣègbọràn sí mi.”
Tàbí “Àwọn àjèjì á pòórá.”
Tàbí “kọ orin sí.”
Tàbí “ìṣẹ́gun.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “Ẹni àrídunnú.”
Tàbí “ìgbàlà.”
Tàbí “ìgbàlà.”
Tàbí “ibùdó àgọ́.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “fọkàn.”
Ní Héb., “ọmọ ọkùnrin kan tó lákíkanjú.”
Tàbí “fi sí Dáfídì lọ́kàn láti.”
Tàbí “gúúsù.”
Tàbí “ẹ̀rí ọkàn.”
Tàbí “kẹ́dùn.”
Ní Héb., “ohun tó bá dára lójú rẹ.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.