KÍRÓNÍKÀ KEJÌ
1 Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ń lágbára sí i nínú ìjọba rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá tó ta yọ.+
2 Sólómọ́nì ránṣẹ́ pe gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, àwọn olórí agbo ilé. 3 Nígbà náà, Sólómọ́nì àti gbogbo ìjọ náà lọ sí ibi gíga tó wà ní Gíbíónì,+ torí pé ibẹ̀ ni àgọ́ ìpàdé Ọlọ́run tòótọ́ wà, èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa ní aginjù. 4 Àmọ́, Dáfídì ti gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá láti Kiriati-jéárímù+ sí ibi tí Dáfídì ṣètò sílẹ̀ fún un; ó ti pa àgọ́ fún un ní Jerúsálẹ́mù.+ 5 Wọ́n ti gbé pẹpẹ bàbà+ tí Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọ Úráì ọmọ Húrì ṣe sí iwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà; Sólómọ́nì àti gbogbo ìjọ sì máa ń gbàdúrà níwájú rẹ̀.* 6 Sólómọ́nì wá rú àwọn ẹbọ níbẹ̀ níwájú Jèhófà, ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹran ẹbọ sísun ló sì fi rúbọ lórí pẹpẹ bàbà+ tó wà ní àgọ́ ìpàdé.
7 Ní òru yẹn, Ọlọ́run fara han Sólómọ́nì, ó sì sọ fún un pé: “Béèrè ohun tí wàá fẹ́ kí n fún ọ.”+ 8 Ni Sólómọ́nì bá sọ fún Ọlọ́run pé: “O ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Dáfídì bàbá mi+ lọ́nà tó ga, o sì ti fi mí jọba ní ipò rẹ̀.+ 9 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run, mú ìlérí tí o ṣe fún Dáfídì bàbá mi ṣẹ,+ nítorí o ti fi mí jọba lórí àwọn èèyàn tó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀.+ 10 Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀+ tí màá fi máa darí àwọn èèyàn yìí,* nítorí ta ló lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ tó pọ̀ yìí?”+
11 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ fún Sólómọ́nì pé: “Nítorí ohun tí ọkàn rẹ fẹ́ yìí àti pé o ò béèrè ọlá, ọrọ̀ àti ògo tàbí ikú* àwọn tó kórìíra rẹ, bẹ́ẹ̀ ni o ò béèrè ẹ̀mí gígùn,* àmọ́ o béèrè ọgbọ́n àti ìmọ̀ kí o lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí,+ 12 màá fún ọ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀; màá tún fún ọ ní ọlá àti ọrọ̀ àti iyì irú èyí tí àwọn ọba tó ṣáájú rẹ kò ní, kò sì ní sí èyí tó máa ní irú rẹ̀ lẹ́yìn rẹ.”+
13 Nítorí náà, Sólómọ́nì dé láti ibi gíga tó wà ní Gíbíónì,+ láti iwájú àgọ́ ìpàdé, sí Jerúsálẹ́mù; ó sì ń ṣàkóso Ísírẹ́lì. 14 Sólómọ́nì ń kó kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin jọ;* ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (1,400) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin,*+ ó sì kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.+ 15 Ọba mú kí fàdákà àti wúrà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pọ̀ rẹpẹtẹ bí òkúta,+ ó sì mú kí igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là.+ 16 Íjíbítì ni wọ́n ti ń kó àwọn ẹṣin wá fún Sólómọ́nì,+ àwùjọ àwọn oníṣòwò ọba á sì ra agbo ẹṣin* náà ní iye kan.+ 17 Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) fàdákà ni wọ́n ń ra kẹ̀kẹ́ ẹṣin kọ̀ọ̀kan láti Íjíbítì, àádọ́jọ (150) fàdákà sì ni wọ́n ń ra ẹṣin kọ̀ọ̀kan; wọ́n á wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo ọba àwọn ọmọ Hétì àti àwọn ọba Síríà.
2 Sólómọ́nì pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà,+ kí wọ́n sì kọ́ ilé* kan fún ìjọba òun.+ 2 Sólómọ́nì yan ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) ọkùnrin láti ṣe lébìrà* àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti máa gé òkúta ní àwọn òkè+ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (3,600) láti ṣe alábòójútó wọn.+ 3 Yàtọ̀ síyẹn, Sólómọ́nì ránṣẹ́ sí Hírámù+ ọba Tírè pé: “Ohun tí o ṣe fún Dáfídì bàbá mi nígbà tí o kó igi kédárì ránṣẹ́ sí i láti fi kọ́ ilé* tí á máa gbé ni kí o ṣe fún mi.+ 4 Ní báyìí, mo fẹ́ kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi, láti yà á sí mímọ́ fún un, láti máa sun tùràrí onílọ́fínńdà+ níwájú rẹ̀ àti láti máa kó búrẹ́dì onípele* síbẹ̀ ní gbogbo ìgbà+ àti àwọn ẹbọ sísun ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́,+ ní àwọn Sábáàtì,+ ní àwọn òṣùpá tuntun+ àti ní àwọn àsìkò àjọyọ̀+ Jèhófà Ọlọ́run wa. Ohun tí Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa ṣe nìyẹn títí láé. 5 Ilé tí mo fẹ́ kọ́ náà máa tóbi, nítorí Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn ọlọ́run míì lọ. 6 Ta ni agbára rẹ̀ gbé e láti kọ́ ilé fún un? Nítorí àwọn ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò lè gbà á,+ ta wá ni mí tí màá fi kọ́ ilé fún un? Àfi kí n kàn kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí ibi tí a ó ti máa mú ẹbọ rú èéfín níwájú rẹ̀. 7 Ní báyìí, fi ọkùnrin oníṣẹ́ ọnà kan ránṣẹ́ sí mi, tó já fáfá nínú iṣẹ́ ọnà wúrà, fàdákà, bàbà,+ irin, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú rírẹ̀dòdò àti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, tó sì mọ bí a ti ń fín àwọn iṣẹ́ ọnà. Ó máa ṣiṣẹ́ ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ọnà mi tó já fáfá, àwọn tí Dáfídì bàbá mi ti pèsè sílẹ̀.+ 8 Kí o kó àwọn gẹdú igi kédárì, ti igi júnípà+ àti ti igi álígọ́mù+ láti Lẹ́bánónì ránṣẹ́ sí mi, nítorí mo mọ̀ dáadáa pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ mọ bí a ṣe ń gé àwọn igi Lẹ́bánónì.+ Àwọn ìránṣẹ́ mi á bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣiṣẹ́+ 9 láti pèsè gẹdú tó pọ̀ gan-an sílẹ̀ fún mi, nítorí ilé tí mo fẹ́ kọ́ máa tóbi yàtọ̀. 10 Wò ó! Màá pèsè oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ,+ àwọn agégi tó máa gé igi náà, màá fún wọn ní: ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* àlìkámà,* ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ọkà bálì, ọ̀kẹ́ kan (20,000) báàtì* wáìnì àti ọ̀kẹ́ kan (20,000) báàtì òróró.”
11 Hírámù ọba Tírè wá kọ̀wé ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì pé: “Nítorí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀, ó fi ọ́ ṣe ọba wọn.” 12 Hírámù sì sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó dá ọ̀run àti ayé, nítorí ó ti fún Ọba Dáfídì ní ọlọ́gbọ́n ọmọ+ tó ní làákàyè àti òye,+ tó máa kọ́ ilé fún Jèhófà àti fún ìjọba òun fúnra rẹ̀. 13 Wò ó, mo ti rán ọkùnrin ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà kan sí ọ, ó ní òye, Hiramu-ábì+ ni orúkọ rẹ̀, 14 ó jẹ́ ọmọ obìnrin kan tó wá látinú ẹ̀yà Dánì, àmọ́ tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ará Tírè; ó já fáfá nínú iṣẹ́ ọnà wúrà, fàdákà, bàbà, irin, òkúta, igi gẹdú, òwú aláwọ̀ pọ́pù, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, aṣọ àtàtà àti aṣọ rírẹ̀dòdò.+ Ó lè fín oríṣiríṣi iṣẹ́ ọnà, ó sì lè ṣe iṣẹ́ ọnà èyíkéyìí tí wọ́n bá fún un.+ Ó máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà rẹ àti àwọn ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà olúwa mi Dáfídì bàbá rẹ. 15 Ní báyìí, kí olúwa mi fi àlìkámà,* ọkà bálì, òróró àti wáìnì tó ṣèlérí ránṣẹ́ sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 16 A máa gé àwọn igi láti Lẹ́bánónì,+ bí èyí tí o nílò bá ṣe pọ̀ tó, a ó kó wọn wá sọ́dọ̀ rẹ ní àdìpọ̀ igi tó léfòó, a ó sì kó wọn gba orí òkun wá sí Jópà;+ wàá sì kó wọn lọ sí Jerúsálẹ́mù.”+
17 Sólómọ́nì wá ka gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ lẹ́yìn ìkànìyàn tí Dáfídì bàbá rẹ̀ ṣe,+ iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́tà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (153,600). 18 Nítorí náà, ó yan ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) lára wọn láti ṣe lébìrà* àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti máa gé òkúta+ ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (3,600) láti ṣe alábòójútó tí á máa kó àwọn èèyàn ṣiṣẹ́.+
3 Nígbà náà, Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé Jèhófà+ sí Jerúsálẹ́mù lórí Òkè Moráyà,+ níbi tí Jèhófà ti fara han Dáfídì bàbá rẹ̀,+ ibẹ̀ ni Dáfídì ṣètò sílẹ̀ ní ibi ìpakà Ọ́nánì+ ará Jébúsì. 2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé náà ní ọjọ́ kejì, oṣù kejì, ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. 3 Ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tòótọ́ tí Sólómọ́nì fi lélẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́,+ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ti tẹ́lẹ̀.* 4 Ibi àbáwọlé* tó wà níwájú jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó bá fífẹ̀ ilé náà mu,* gíga rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; * ó wá fi ògidì wúrà bò ó nínú.+ 5 Ó fi igi júnípà bo ilé ńlá náà, lẹ́yìn náà, ó fi wúrà tó dára bò ó,+ ó wá ya àwòrán igi ọ̀pẹ+ àti ẹ̀wọ̀n+ sára rẹ̀. 6 Yàtọ̀ síyẹn, ó fi òkúta iyebíye tó rẹwà+ bo ilé náà; wúrà+ tó lò sì jẹ́ wúrà láti Páfáímù. 7 Ó fi wúrà bo ilé náà àti àwọn igi ìrólé rẹ̀, ó tún fi bo àwọn ibi àbáwọlé rẹ̀,+ àwọn ògiri rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀; ó sì fín àwọn kérúbù sára àwọn ògiri náà.+
8 Ó ṣe apá* Ibi Mímọ́ Jù Lọ,+ gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé náà mu, ó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́. Ó fi ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) tálẹ́ńtì* wúrà tó dára bò ó.+ 9 Ìwọ̀n wúrà fún ìṣó jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì;* ó sì fi wúrà bo àwọn yàrá orí òrùlé.
10 Lẹ́yìn náà, ó ṣe ère kérúbù méjì sínú apá* Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ó sì fi wúrà bò wọ́n.+ 11 Gígùn ìyẹ́ apá àwọn kérúbù+ náà lápapọ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; ìyẹ́ apá kan kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ògiri ilé náà, ìyẹ́ apá rẹ̀ kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ìyẹ́ apá kérúbù kejì. 12 Ìyẹ́ apá kan kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ògiri kejì ilé náà, ìyẹ́ apá rẹ̀ kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ọ̀kan lára ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́. 13 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù yìí nà jáde ní ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; wọ́n sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí inú.*
14 Bákan náà, ó fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú rírẹ̀dòdò àti aṣọ àtàtà ṣe aṣọ ìdábùú,+ ó sì ṣe iṣẹ́ ọnà kérúbù sí i lára.+
15 Lẹ́yìn náà, ó ṣe òpó méjì+ síwájú ilé náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùndínlógójì (35), ọpọ́n tó wà lórí òpó kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.+ 16 Ó ṣe àwọn ẹ̀wọ̀n tó dà bí ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn, ó sì fi wọ́n sórí àwọn òpó náà, ó ṣe ọgọ́rùn-ún (100) pómégíránétì, ó sì fi wọ́n sára àwọn ẹ̀wọ̀n náà. 17 Ó ṣe àwọn òpó náà síwájú tẹ́ńpìlì, ọ̀kan sápá ọ̀tún,* èkejì sápá òsì;* ó pe èyí tó wà lápá ọ̀tún ní Jákínì* àti èyí tó wà lápá òsì ní Bóásì.*
4 Lẹ́yìn náà, ó ṣe pẹpẹ bàbà,+ gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.
2 Ó fi irin ṣe Òkun.*+ Ó rí ribiti, fífẹ̀ ẹnu rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, okùn ìdíwọ̀n ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́ ló sì lè yí i ká.+ 3 Àwọn iṣẹ́ ọnà tó rí bí akèrègbè+ wà nísàlẹ̀ rẹ̀ yí ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan, wọ́n yí Òkun náà po. Àwọn iṣẹ́ ọnà tó rí bí akèrègbè náà wà ní ìlà méjì, ó sì ṣe é mọ́ ọn lára. 4 Wọ́n gbé Òkun náà ka orí akọ màlúù méjìlá (12),+ mẹ́ta dojú kọ àríwá, mẹ́ta dojú kọ ìwọ̀ oòrùn, mẹ́ta dojú kọ gúúsù, mẹ́ta sì dojú kọ ìlà oòrùn; Òkun náà wà lórí wọn, gbogbo wọn sì kọ̀dí sí abẹ́ Òkun náà. 5 Ìnípọn rẹ̀ jẹ́ ìbú ọwọ́ kan;* ẹnu rẹ̀ sì dà bí ẹnu ife, bí ìtànná òdòdó lílì. Agbada ńlá náà lè gba ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) báàtì* omi.
6 Síwájú sí i, ó ṣe bàsíà mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó gbé márùn-ún sí apá ọ̀tún àti márùn-ún sí apá òsì.+ Inú wọn ni wọ́n ti ń ṣan àwọn ohun tí wọ́n ń lò fún ẹbọ sísun.+ Àmọ́ Òkun náà jẹ́ ti àwọn àlùfáà láti máa fi wẹ apá àti ẹsẹ̀ wọn.+
7 Lẹ́yìn náà, ó ṣe ọ̀pá fìtílà wúrà mẹ́wàá+ bó ṣe wà nínú àwòrán,+ ó sì gbé wọn sínú tẹ́ńpìlì, márùn-ún sí apá ọ̀tún àti márùn-ún sí apá òsì.+
8 Ó tún ṣe tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sínú tẹ́ńpìlì, márùn-ún sí apá ọ̀tún àti márùn-ún sí apá òsì;+ ó sì ṣe ọgọ́rùn-ún (100) abọ́ wúrà.
9 Ó wá ṣe àgbàlá+ àwọn àlùfáà+ àti àgbàlá ńlá* pẹ̀lú àwọn ilẹ̀kùn àgbàlá náà,+ ó sì fi bàbà bo àwọn ilẹ̀kùn wọn. 10 Ó gbé Òkun náà sí apá ọ̀tún, láàárín gúúsù àti ìlà oòrùn.+
11 Hírámù tún ṣe àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn abọ́.+
Bẹ́ẹ̀ ni Hírámù parí iṣẹ́ tó ṣe fún Ọba Sólómọ́nì ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, ìyẹn:+ 12 àwọn òpó méjèèjì+ àti àwọn ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí òpó méjèèjì; iṣẹ́ ọnà méjèèjì+ tó dà bí àwọ̀n tó fi bo ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí àwọn òpó náà; 13 ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) pómégíránétì+ fún iṣẹ́ ọnà méjì tó dà bí àwọ̀n, ìlà méjì pómégíránétì fún iṣẹ́ ọnà kọ̀ọ̀kan tó dà bí àwọ̀n, tó fi bo ọpọ́n méjèèjì tó rí bí abọ́ lórí àwọn òpó;+ 14 kẹ̀kẹ́ ẹrù* mẹ́wẹ̀ẹ̀wá àti bàsíà mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tó wà lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù náà;+ 15 Òkun náà àti akọ màlúù méjìlá (12) tó wà lábẹ́ rẹ̀;+ 16 àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn àmúga+ àti gbogbo àwọn nǹkan èlò wọn ni Hiramu-ábífì+ fi bàbà dídán ṣe fún Ọba Sólómọ́nì fún ilé Jèhófà. 17 Agbègbè Jọ́dánì ni ọba ti rọ wọ́n ní ilẹ̀ amọ̀ tó ki, èyí tó wà láàárín Súkótù+ àti Sérédà. 18 Sólómọ́nì ṣe gbogbo nǹkan èlò yìí, wọ́n sì pọ̀ gan-an; a kò mọ bí ìwọ̀n bàbà náà ṣe pọ̀ tó.+
19 Sólómọ́nì ṣe gbogbo nǹkan èlò+ ilé Ọlọ́run tòótọ́: pẹpẹ wúrà;+ àwọn tábìlì+ tí búrẹ́dì àfihàn wà lórí wọn;+ 20 àwọn ọ̀pá fìtílà àti fìtílà wọn tí a fi ògidì wúrà ṣe,+ tí á máa jó níwájú yàrá inú lọ́hùn-ún gẹ́gẹ́ bí ìlànà ṣe sọ; 21 àwọn ìtànná òdòdó, àwọn fìtílà, àwọn ìpaná* tí a fi wúrà ṣe, tó jẹ́ ògidì wúrà pọ́ńbélé; 22 àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn abọ́, àwọn ife àti àwọn ìkóná tí a fi ògidì wúrà ṣe; ẹnu ọ̀nà ilé náà, àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ ti inú Ibi Mímọ́ Jù Lọ+ àti àwọn ilẹ̀kùn ilé tẹ́ńpìlì tí a fi wúrà ṣe.+
5 Níkẹyìn, Sólómọ́nì parí gbogbo iṣẹ́ ilé Jèhófà tó yẹ ní ṣíṣe.+ Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì kó àwọn ohun tí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wọlé,+ ó kó fàdákà, wúrà àti gbogbo ohun èlò wá sínú ibi ìṣúra ilé Ọlọ́run tòótọ́.+ 2 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, gbogbo olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí agbo ilé ní Ísírẹ́lì. Wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti Ìlú Dáfídì,+ ìyẹn Síónì.+ 3 Gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì pé jọ síwájú ọba nígbà àjọyọ̀* tí wọ́n ń ṣe ní oṣù keje.+
4 Nítorí náà, gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì wá, àwọn ọmọ Léfì sì gbé Àpótí náà.+ 5 Wọ́n gbé Àpótí náà àti àgọ́ ìpàdé + wá pẹ̀lú gbogbo nǹkan èlò mímọ́ tó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì* ló gbé wọn wá. 6 Ọba Sólómọ́nì àti gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì, ìyẹn àwọn tó ní kí wọ́n pàdé òun, wà níwájú Àpótí náà. Àgùntàn àti màlúù tí wọ́n fi rúbọ+ pọ̀ débi pé wọn ò ṣeé kà, wọn ò sì níye. 7 Nígbà náà, àwọn àlùfáà gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà wá sí àyè rẹ̀, ní yàrá inú lọ́hùn-ún ilé náà, ìyẹn Ibi Mímọ́ Jù Lọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ apá àwọn kérúbù.+ 8 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà nà jáde sórí ibi tí Àpótí náà wà, tó fi jẹ́ pé àwọn kérúbù náà bo Àpótí náà àti àwọn ọ̀pá rẹ̀+ láti òkè. 9 Àwọn ọ̀pá náà gùn débi pé a lè rí orí wọn láti Ibi Mímọ́ ní iwájú yàrá inú lọ́hùn-ún, ṣùgbọ́n a kò lè rí wọn láti òde. Wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí. 10 Kò sí nǹkan míì nínú Àpótí náà àfi wàláà méjì tí Mósè kó sínú rẹ̀ ní Hórébù,+ nígbà tí Jèhófà bá àwọn èèyàn Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú+ bí wọ́n ṣe ń jáde bọ̀ láti Íjíbítì.+
11 Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti ibi mímọ́ (nítorí gbogbo àwọn àlùfáà tó wà níbẹ̀ ni wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́,+ láìka àwùjọ tí wọ́n wà sí),+ 12 gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ akọrin+ tí wọ́n jẹ́ ti Ásáfù,+ ti Hémánì,+ ti Jédútúnì + àti ti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn ló wọ aṣọ àtàtà, síńbálì* wà lọ́wọ́ wọn àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù; wọ́n dúró sí apá ìlà oòrùn pẹpẹ, àwọn pẹ̀lú ọgọ́fà (120) àlùfáà tó ń fun kàkàkí.+ 13 Gbàrà tí àwọn tó ń fun kàkàkí àti àwọn akọrin bẹ̀rẹ̀ sí í yin Jèhófà, tí wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ohùn tó ṣọ̀kan, tí ìró kàkàkí àti síńbálì pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin míì ń dún sókè bí wọ́n ṣe ń yin Jèhófà, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì wà títí láé,”+ ni ìkùukùu+ bá kún inú ilé náà, ìyẹn ilé Jèhófà. 14 Àwọn àlùfáà kò lè dúró ṣe iṣẹ́ wọn nítorí ìkùukùu náà, torí pé ògo Jèhófà kún inú ilé Ọlọ́run tòótọ́.+
6 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì sọ̀rọ̀, ó ní: “Jèhófà sọ pé inú ìṣúdùdù tó kàmàmà+ ni òun á máa gbé. 2 Ní báyìí, mo ti kọ́ ilé ológo kan fún ọ, ibi tó fìdí múlẹ̀ tí wàá máa gbé títí láé.”+
3 Lẹ́yìn náà, ọba yíjú pa dà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í súre fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, bí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì ṣe wà ní ìdúró.+ 4 Ó sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó fi ẹnu ara rẹ̀ ṣèlérí fún Dáfídì bàbá mi, tó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un ṣẹ, tó sọ pé, 5 ‘Láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn èèyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mi ò yan ìlú kankan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí màá kọ́ ilé sí fún orúkọ mi, kí ó lè máa wà níbẹ̀,+ mi ò sì yan ọkùnrin kankan láti jẹ́ aṣáájú lórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì. 6 Ṣùgbọ́n mo ti yan Jerúsálẹ́mù+ kí orúkọ mi lè máa wà níbẹ̀, mo sì ti yan Dáfídì láti ṣe olórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’+ 7 Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn Dáfídì bàbá mi pé kí ó kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 8 Àmọ́, Jèhófà sọ fún Dáfídì bàbá mi pé, ‘Ìfẹ́ ọkàn rẹ ni pé kí o kọ́ ilé fún orúkọ mi, ó sì dára bó ṣe ń wù ọ́ yìí. 9 Ṣùgbọ́n, ìwọ kọ́ ló máa kọ́ ilé náà, ọmọ tí o máa bí* ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.’+ 10 Jèhófà ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, torí mo ti jọba ní ipò Dáfídì bàbá mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì,+ bí Jèhófà ti ṣèlérí.+ Mo tún kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, 11 ibẹ̀ ni mo sì gbé Àpótí tí májẹ̀mú+ Jèhófà wà nínú rẹ̀ sí, èyí tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá.”
12 Ó wá dúró níwájú pẹpẹ Jèhófà ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ síwájú.+ 13 (Sólómọ́nì ṣe pèpéle bàbà, ó sì gbé e sí àárín àgbàlá.*+ Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* márùn-ún, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta; ó sì dúró sórí rẹ̀.) Ó kúnlẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀run,+ 14 ó wá sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tó dà bí rẹ ní ọ̀run tàbí ní ayé, ò ń pa májẹ̀mú mọ́, o sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tó ń fi gbogbo ọkàn+ wọn rìn níwájú rẹ. 15 O ti mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ.+ Ẹnu rẹ lo fi ṣe ìlérí náà, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú un ṣẹ lónìí yìí.+ 16 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ, nígbà tí o sọ pé: ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ níwájú mi tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, bí àwọn ọmọ rẹ bá ṣáà ti ń fiyè sí ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì ń rìn nínú òfin mi+ bí ìwọ náà ṣe rìn níwájú mi.’+ 17 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì ṣẹ.
18 “Àmọ́, ṣé Ọlọ́run á máa bá àwọn èèyàn gbé inú ayé ni?+ Wò ó! Àwọn ọ̀run, àní, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́;+ ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ilé tí mo kọ́ yìí!+ 19 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi, fiyè sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, kí o sì fetí sí igbe ìránṣẹ́ rẹ fún ìrànlọ́wọ́ àti àdúrà tó ń gbà níwájú rẹ. 20 Kí ojú rẹ wà lára ilé yìí tọ̀sántòru, lára ibi tí o sọ pé wàá fi orúkọ rẹ sí,+ láti fetí sí àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní ìdojúkọ ibí yìí. 21 Kí o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ fún ìrànlọ́wọ́ àti ẹ̀bẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí,+ kí o gbọ́ láti ibi tí ò ń gbé, láti ọ̀run;+ kí o gbọ́, kí o sì dárí jì wọ́n.+
22 “Tí ẹnì kan bá ṣẹ ọmọnìkejì rẹ̀, tó mú kó búra,* tó sì mú kó wà lábẹ́ ìbúra* náà, tó bá wá síwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí+ nígbà tó ṣì wà lábẹ́ ìbúra* náà, 23 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o gbé ìgbésẹ̀, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kí o san ẹni burúkú lẹ́san, kí o sì jẹ́ kí ohun tó ṣe dà lé e lórí,+ kí o pe olódodo ní aláìṣẹ̀,* kí o sì san èrè òdodo rẹ̀ fún un.+
24 “Tí ọ̀tá bá ṣẹ́gun àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n sì pa dà wá, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga,+ tí wọ́n gbàdúrà,+ tí wọ́n sì bẹ̀ ọ́ nínú ilé yìí pé kí o ṣojú rere sí àwọn,+ 25 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run,+ kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì jì wọ́n, kí o sì mú wọn pa dà wá sí ilẹ̀ tí o fún àwọn àti àwọn baba ńlá wọn.+
26 “Nígbà tí ọ̀run bá sé pa, tí òjò kò sì rọ̀ + torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga, tí wọ́n sì yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé o rẹ̀ wọ́n wálẹ̀,*+ 27 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, ìyẹn àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé wàá tọ́ wọn sí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa rìn;+ kí o sì rọ̀jò+ sórí ilẹ̀ rẹ tí o fún àwọn èèyàn rẹ láti jogún.
28 “Bí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ náà+ tàbí tí àjàkálẹ̀ àrùn+ bá jà, tí ooru tó ń jó ewéko gbẹ tàbí èbíbu+ bá wà, tí ọ̀wọ́ eéṣú tàbí ọ̀yánnú eéṣú*+ bá wà tàbí tí àwọn ọ̀tá wọn bá dó tì wọ́n ní ìlú èyíkéyìí ní ilẹ̀ náà*+ tàbí tí ìyọnu èyíkéyìí tàbí àrùn bá wáyé,+ 29 àdúrà+ èyíkéyìí tí ì báà jẹ́, ìbéèrè fún ojú rere+ èyíkéyìí tí ẹnikẹ́ni bá béèrè tàbí èyí tí gbogbo àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì bá béèrè (nítorí pé kálukú ló mọ ìṣòro rẹ̀ àti ìrora rẹ̀),+ tí wọ́n bá tẹ́ ọwọ́ wọn sí apá ibi tí ilé yìí wà,+ 30 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé,+ kí o sì dárí jì wọ́n;+ kí o san èrè fún kálukú gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ̀, nítorí pé o mọ ọkàn rẹ̀ (ìwọ nìkan lo mọ ọkàn èèyàn),+ 31 kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n á fi gbé lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wa.
32 “Bákan náà, ní ti àjèjì tí kì í ṣe ara àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, àmọ́ tó wá láti ilẹ̀ tó jìnnà nítorí orúkọ ńlá rẹ*+ àti ọwọ́ agbára rẹ pẹ̀lú apá rẹ tó nà jáde, tí ó sì wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ilé yìí,+ 33 nígbà náà, kí o fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé, kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo aráyé lè mọ orúkọ rẹ,+ kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ, bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì ti ń ṣe, kí wọ́n sì mọ̀ pé a ti fi orúkọ rẹ pe ilé tí mo kọ́ yìí.
34 “Tí àwọn èèyàn rẹ bá lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà lójú ogun bí o ṣe rán wọn,+ tí wọ́n sì gbàdúrà + sí ọ ní ìdojúkọ ìlú tí o yàn àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+ 35 nígbà náà, kí o gbọ́ àdúrà wọn láti ọ̀run àti ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí o ṣojú rere sí àwọn, kí o sì ṣe ìdájọ́ nítorí wọn.+
36 “Tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí kò sí èèyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀),+ tí inú rẹ ru sí wọn, tí o fi wọ́n sílẹ̀ fún ọ̀tá, tí àwọn tó mú wọn sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ kan, bóyá èyí tó jìnnà tàbí èyí tó wà nítòsí,+ 37 tí wọ́n bá ro inú ara wọn wò ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o ṣojú rere sí àwọn ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ ẹrú, tí wọ́n sọ pé, ‘A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣàṣìṣe; a ti ṣe ohun búburú,’+ 38 tí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn+ wọn àti gbogbo ara* wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣe ẹrú,+ ìyẹn ibi tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà ní ìdojúkọ ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn àti ìlú tí o yàn+ àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ, 39 nígbà náà, láti ibi tí ò ń gbé ní ọ̀run, kí o gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí o ṣojú rere sí àwọn,+ kí o sì ṣe ìdájọ́ nítorí wọn, kí o dárí ji àwọn èèyàn rẹ tó ṣẹ̀ ọ́.
40 “Ní báyìí, ìwọ Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, ṣí ojú rẹ, kí o sì tẹ́tí sí àdúrà tí a bá gbà ní* ibí yìí.+ 41 Torí náà, dìde, Jèhófà Ọlọ́run, wá síbi ìsinmi rẹ,+ ìwọ àti Àpótí agbára rẹ. Jèhófà Ọlọ́run, fi aṣọ ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ, sì jẹ́ kí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yọ̀ nínú ohun rere.+ 42 Jèhófà Ọlọ́run, má ṣe kọ ẹni àmì òróró rẹ sílẹ̀.*+ Rántí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ.”+
7 Gbàrà tí Sólómọ́nì parí àdúrà rẹ̀,+ iná bọ́ láti ọ̀run,+ ó jó ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ náà, ògo Jèhófà sì kún ilé náà.+ 2 Àwọn àlùfáà kò lè wọnú ilé Jèhófà nítorí pé ògo Jèhófà ti kún ilé Jèhófà.+ 3 Gbogbo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ń wò nígbà tí iná bọ́ sílẹ̀, tí ògo Jèhófà sì bo ilé náà, wọ́n tẹrí ba, wọ́n sì dojú bolẹ̀ lórí ibi tí a fi òkúta tẹ́, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì wà títí láé.”
4 Ọba àti gbogbo àwọn èèyàn náà rú àwọn ẹbọ níwájú Jèhófà.+ 5 Ọba Sólómọ́nì fi ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) màlúù àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn rúbọ. Bí ọba àti gbogbo àwọn èèyàn náà ṣe ṣayẹyẹ ṣíṣí ilé Ọlọ́run tòótọ́ nìyẹn.+ 6 Àwọn àlùfáà dúró sí ibi iṣẹ́ wọn, bí àwọn ọmọ Léfì náà ṣe dúró pẹ̀lú ohun èlò tí wọ́n fi ń kọrin sí Jèhófà.+ (Ọba Dáfídì ṣe àwọn ohun ìkọrin yìí láti máa fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, nígbà tí Dáfídì bá ń yin Ọlọ́run pẹ̀lú wọn,* “nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”) Àwọn àlùfáà ń fun kàkàkí kíkankíkan+ níwájú wọn, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì wà ní ìdúró.
7 Nígbà náà, Sólómọ́nì ya àárín àgbàlá tó wà níwájú ilé Jèhófà sí mímọ́, torí ibẹ̀ ló ti máa rú àwọn ẹbọ sísun+ àti àwọn apá tó lọ́ràá lára àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀, nítorí pé pẹpẹ bàbà+ tí Sólómọ́nì ṣe kò lè gba àwọn ẹbọ sísun náà àti ọrẹ ọkà+ pẹ̀lú àwọn apá tó lọ́ràá.+ 8 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì fi ọjọ́ méje+ ṣe àjọyọ̀ náà pẹ̀lú gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n jẹ́ ìjọ ńlá láti Lebo-hámátì* títí dé Àfonífojì Íjíbítì.+ 9 Àmọ́ ní ọjọ́ kẹjọ,* wọ́n ṣe àpéjọ ọlọ́wọ̀,+ nítorí pé wọ́n ti fi ọjọ́ méje ṣe ayẹyẹ ṣíṣí pẹpẹ náà, wọ́n sì ti fi ọjọ́ méje ṣe àjọyọ̀. 10 Nígbà tó di ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù keje, ó ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ sí ilé wọn, inú wọn ń dùn,+ ayọ̀ sì kún ọ̀kan wọn nítorí oore tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì àti Sólómọ́nì pẹ̀lú Ísírẹ́lì àwọn èèyàn rẹ̀.+
11 Bí Sólómọ́nì ṣe parí ilé Jèhófà àti ilé* ọba nìyẹn;+ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn Sólómọ́nì láti ṣe nípa ilé Jèhófà àti ilé tirẹ̀ ló ṣe láṣeyọrí.+ 12 Jèhófà wá fara han Sólómọ́nì+ ní òru, ó sì sọ fún un pé: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ, mo sì ti yan ibí yìí fún ara mi láti jẹ́ ilé ìrúbọ.+ 13 Nígbà tí mo bá sé ọ̀run pa, tí òjò kò sì rọ̀, nígbà tí mo bá pàṣẹ fún àwọn tata láti jẹ ilẹ̀ náà run, tí mo bá sì rán àjàkálẹ̀ àrùn sáàárín àwọn èèyàn mi, 14 tí àwọn èèyàn mi tí à ń fi orúkọ mi pè+ sì rẹ ara wọn sílẹ̀,+ tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n wá ojú mi, tí wọ́n sì kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn,+ nígbà náà, màá gbọ́ láti ọ̀run, màá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, màá sì wo ilẹ̀ wọn sàn.+ 15 Ní báyìí, màá la ojú mi, màá sì tẹ́tí sí àdúrà tí wọ́n bá gbà ní ibí yìí.+ 16 Mo ti yan ilé yìí, mo sì yà á sí mímọ́ kí orúkọ mi lè máa wà níbẹ̀ títí lọ,+ ojú mi àti ọkàn mi á sì máa wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.+
17 “Ní tìrẹ, tí o bá rìn níwájú mi bí Dáfídì bàbá rẹ ṣe rìn, tí ò ń ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ, tí o sì ń pa àwọn ìlànà mi àti àwọn ìdájọ́ mi mọ́,+ 18 ìgbà náà ni màá fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀,+ bí mo ṣe bá Dáfídì bàbá rẹ dá májẹ̀mú pé,+ ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ tí yóò máa ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì.’+ 19 Àmọ́ tí ẹ bá pa dà lẹ́yìn mi, tí ẹ kò sì pa àwọn òfin àti àṣẹ tí mo fún yín mọ́, tí ẹ wá lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ sì ń forí balẹ̀ fún wọn,+ 20 ńṣe ni màá fa Ísírẹ́lì tu lórí ilẹ̀ mi tí mo fún wọn,+ màá gbé ilé yìí tí mo yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sọ nù kúrò níwájú mi, màá sọ ọ́ di ohun ẹ̀gàn* àti ohun ẹ̀sín láàárín gbogbo èèyàn.+ 21 Ilé yìí á di àwókù. Gbogbo ẹni tó bá gba ibẹ̀ kọjá á wò ó tìyanutìyanu,+ á sì sọ pé, ‘Kì nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+ 22 Nígbà náà, wọ́n á sọ pé, ‘Torí pé wọ́n fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀ ni,+ ẹni tó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ wọ́n yíjú sí àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń forí balẹ̀ fún wọn,+ wọ́n sì ń sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tó fi mú gbogbo àjálù yìí bá wọn.’”+
8 Ní òpin ogún (20) ọdún tí Sólómọ́nì fi kọ́ ilé Jèhófà àti ilé ara rẹ̀,*+ 2 Sólómọ́nì tún àwọn ìlú tí Hírámù+ fún un kọ́, ó sì ní kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* máa gbé ibẹ̀. 3 Yàtọ̀ síyẹn, Sólómọ́nì lọ sí Hamati-sóbà, ó sì gbà á. 4 Lẹ́yìn náà, ó kọ́ Tádímórì ní aginjù* àti gbogbo àwọn ìlú tí ó ń kó nǹkan pa mọ́ sí,+ èyí tó kọ́ sí Hámátì.+ 5 Ó tún kọ́ Bẹti-hórónì Òkè+ àti Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀,+ àwọn ìlú aláàbò tó ní ògiri àti àwọn ẹnubodè pẹ̀lú ọ̀pá ìdábùú. 6 Bákan náà, ó kọ́ Báálátì+ pẹ̀lú gbogbo àwọn ìlú tó ń kó nǹkan pa mọ́ sí, gbogbo àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ àwọn ìlú àwọn agẹṣin àti ohunkóhun tó wu Sólómọ́nì láti kọ́ sí Jerúsálẹ́mù, sí Lẹ́bánónì àti sí gbogbo ilẹ̀ tó ń ṣàkóso lé lórí.
7 Ní ti gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ tí wọn kì í ṣe ara àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ 8 àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò pa run,+ Sólómọ́nì ní kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ fún òun títí di òní yìí.+ 9 Àmọ́ Sólómọ́nì kò fi ọmọ Ísírẹ́lì kankan ṣe ẹrú fún iṣẹ́ rẹ̀,+ àwọn ló fi ṣe jagunjagun rẹ̀, olórí àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun rẹ̀, olórí àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ti àwọn agẹṣin rẹ̀.+ 10 Olórí àwọn alábòójútó fún Ọba Sólómọ́nì jẹ́ igba ó lé àádọ́ta (250), àwọn ló sì ń darí àwọn èèyàn náà.+
11 Bákan náà, Sólómọ́nì mú ọmọbìnrin Fáráò+ wá láti Ìlú Dáfídì sí ilé tó kọ́ fún un,+ torí ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó mi ni, kò yẹ kó máa gbé inú ilé Dáfídì ọba Ísírẹ́lì, nítorí ibi tí Àpótí Jèhófà bá ti wọ̀ ti di mímọ́.”+
12 Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì rú àwọn ẹbọ sísun+ sí Jèhófà lórí pẹpẹ+ Jèhófà tí ó mọ síwájú ibi àbáwọlé.*+ 13 Ó ń ṣe ohun tí wọ́n máa ń ṣe lójoojúmọ́, ó sì ń mú ọrẹ wá gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Mósè pa ní ti àwọn Sábáàtì,+ àwọn òṣùpá tuntun+ àti àwọn àjọyọ̀ tó máa ń wáyé nígbà mẹ́ta lọ́dún,+ ìyẹn Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀+ àti Àjọyọ̀ Àtíbàbà.+ 14 Síwájú sí i, ó yan àwùjọ àwọn àlùfáà+ sí àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dáfídì bàbá rẹ̀ fi lélẹ̀, ó yan àwọn ọmọ Léfì sẹ́nu iṣẹ́ wọn, láti máa yin+ Ọlọ́run àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú àwọn àlùfáà bí wọ́n ti ń ṣe lójoojúmọ́, ó tún yan àwùjọ àwọn aṣọ́bodè sí ẹnubodè kọ̀ọ̀kan,+ nítorí ohun tí Dáfídì, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ nìyẹn. 15 Wọn ò kúrò nínú àṣẹ tí ọba pa fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì nínú ọ̀ràn èyíkéyìí tàbí ní ti ilé ìkẹ́rùsí. 16 Nítorí náà, gbogbo iṣẹ́ Sólómọ́nì wà létòlétò,* láti ọjọ́ tí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀+ títí ó fi parí. Bí ilé Jèhófà ṣe parí nìyẹn.+
17 Ìgbà náà ni Sólómọ́nì lọ sí Esioni-gébérì+ àti sí Élótì+ ní èbúté òkun tó wà ní ilẹ̀ Édómù.+ 18 Hírámù+ fi àwọn ọkọ̀ òkun àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òkun tó mọṣẹ́ ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Wọ́n bá àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì lọ sí Ófírì,+ wọ́n sì kó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (450) tálẹ́ńtì* wúrà+ láti ibẹ̀ wá fún Ọba Sólómọ́nì.+
9 Ọbabìnrin Ṣébà+ gbọ́ ìròyìn Sólómọ́nì, torí náà ó wá sí Jerúsálẹ́mù, kó lè fi àwọn ìbéèrè tó ta kókó* dán an wò. Àwọn abọ́barìn* tó gbayì ló tẹ̀ lé e pẹ̀lú àwọn ràkúnmí tó ru òróró básámù àti wúrà tó pọ̀ gan-an+ àti àwọn òkúta iyebíye. Ó lọ sọ́dọ̀ Sólómọ́nì, ó sì bá a sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.+ 2 Sólómọ́nì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Kò sí ohun tó ṣòro* fún Sólómọ́nì láti ṣàlàyé fún un.
3 Nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà rí ọgbọ́n Sólómọ́nì+ àti ilé tó kọ́,+ 4 oúnjẹ orí tábìlì rẹ̀,+ bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń jókòó, bó ṣe ṣètò iṣẹ́ àwọn tó ń gbé oúnjẹ fún un àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, àwọn agbọ́tí rẹ̀ àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbọ sísun tó ń rú déédéé ní ilé Jèhófà,+ ẹnu yà á gan-an.* 5 Nítorí náà, ó sọ fún ọba pé: “Òótọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ilẹ̀ mi nípa àwọn àṣeyọrí* rẹ àti ọgbọ́n rẹ. 6 Àmọ́ mi ò gba ìròyìn náà gbọ́ títí mo fi wá fojú ara mi rí i.+ Wò ó! Ohun tí mo gbọ́ nípa ọ̀pọ̀ ọgbọ́n tí o ní kò tiẹ̀ tó ìdajì rárá.+ O ti ré kọjá àwọn ohun tí mo gbọ́ nípa rẹ.+ 7 Aláyọ̀ ni àwọn èèyàn rẹ, aláyọ̀ sì ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fetí sí ọgbọ́n rẹ! 8 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí ọ tó fi gbé ọ gorí ìtẹ́ rẹ̀ láti jẹ́ ọba fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Torí pé Ọlọ́run rẹ nífẹ̀ẹ́ Ísírẹ́lì,+ ó fi ọ́ jọba lé e lórí láti máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ àti láti máa ṣe òdodo, kó lè mú kí Ísírẹ́lì máa wà títí lọ.”
9 Lẹ́yìn náà, ó fún ọba ní ọgọ́fà (120) tálẹ́ńtì* wúrà+ àti òróró básámù tó pọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye. Kò tún sẹ́ni tó kó irú òróró básámù tó pọ̀ wọlé bí èyí tí ọbabìnrin Ṣébà kó wá fún Ọba Sólómọ́nì.+
10 Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìránṣẹ́ Hírámù àti àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì tí wọ́n kó wúrà wá láti Ófírì+ tún kó àwọn gẹdú igi álígọ́mù àti àwọn òkúta iyebíye wá.+ 11 Ọba fi àwọn gẹdú igi álígọ́mù náà ṣe àtẹ̀gùn sí ilé Jèhófà+ àti sí ilé* ọba,+ títí kan àwọn háàpù àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín fún àwọn akọrin.+ A kò rí irú àwọn nǹkan yìí rí ní ilẹ̀ Júdà.
12 Ọba Sólómọ́nì náà fún ọbabìnrin Ṣébà ní gbogbo ohun tó fẹ́ àti ohun tó béèrè, ohun tó fún un ju* ohun tó kó wá fún ọba. Lẹ́yìn náà, ó kúrò níbẹ̀, ó sì pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+
13 Ìwọ̀n wúrà tí wọ́n ń kó wá fún Sólómọ́nì lọ́dọọdún jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgọ́ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ńtì wúrà,+ 14 yàtọ̀ sí ohun tí àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà ń kó wá, títí kan wúrà àti fàdákà tí gbogbo àwọn ọba ará Arébíà àti àwọn gómìnà ilẹ̀ náà ń kó wá fún Sólómọ́nì.+
15 Ọba Sólómọ́nì fi àyọ́pọ̀ wúrà ṣe igba (200) apata ńlá,+ (ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ṣékélì* àyọ́pọ̀ wúrà ni ó lò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn),+ 16 ó sì fi àyọ́pọ̀ wúrà ṣe ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) asà* (wúrà mínà* mẹ́ta ni ó lò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn). Lẹ́yìn náà, ọba kó wọn sínú Ilé Igbó Lẹ́bánónì.+
17 Ọba tún fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan, ó sì fi ògidì wúrà bò ó.+ 18 Àtẹ̀gùn mẹ́fà ni ìtẹ́ náà ní, àpótí ìtìsẹ̀ tí wọ́n fi wúrà ṣe tún wà lára ìtẹ́ náà, ibi ìgbápálé wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ìjókòó náà, ère kìnnìún+ kọ̀ọ̀kan sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ibi ìgbápálé náà. 19 Àwọn kìnnìún+ tó dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́fà náà jẹ́ méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní eteetí àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan. Kò sí ìjọba kankan tó ṣe irú rẹ̀ rí. 20 Gbogbo ohun èlò tí Ọba Sólómọ́nì fi ń mu nǹkan jẹ́ wúrà, gbogbo ohun èlò Ilé Igbó Lẹ́bánónì sì jẹ́ ògidì wúrà. Kò sí ìkankan tí wọ́n fi fàdákà ṣe, nítorí fàdákà kò já mọ́ nǹkan kan nígbà ayé Sólómọ́nì.+ 21 Àwọn ọkọ̀ òkun ọba máa ń lọ sí Táṣíṣì+ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Hírámù.+ Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹ́ta ni àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì máa ń kó wúrà àti fàdákà, eyín erin,+ àwọn ìnàkí àti àwọn ẹyẹ ọ̀kín wọlé.
22 Nítorí náà, ọrọ̀ àti ọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì pọ̀ ju ti gbogbo àwọn ọba yòókù láyé.+ 23 Àwọn ọba láti ibi gbogbo láyé ń wá sọ́dọ̀* Sólómọ́nì kí wọ́n lè gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run fi sí i lọ́kàn.+ 24 Kálukú wọn ń mú ẹ̀bùn wá, ìyẹn àwọn ohun èlò fàdákà, àwọn ohun èlò wúrà, àwọn aṣọ,+ ìhámọ́ra, òróró básámù, àwọn ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* wọ́n sì ń mú wọn wá lọ́dọọdún. 25 Sólómọ́nì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ilé ẹṣin fún àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin,*+ ó kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.+ 26 Ó ṣàkóso gbogbo àwọn ọba láti Odò* títí dé ilẹ̀ àwọn Filísínì àti títí dé ààlà Íjíbítì.+ 27 Ọba mú kí fàdákà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pọ̀ rẹpẹtẹ bí òkúta, ó sì mú kí igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là.+ 28 Wọ́n máa ń kó ẹṣin wá fún Sólómọ́nì láti Íjíbítì+ àti láti gbogbo àwọn ilẹ̀ yòókù.
29 Ní ti ìyókù ìtàn Sólómọ́nì,+ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ wòlíì Nátánì,+ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Áhíjà+ ọmọ Ṣílò àti nínú àkọsílẹ̀ àwọn ìran Ídò+ aríran tó sọ nípa Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì? 30 Sólómọ́nì fi ogójì (40) ọdún jọba ní Jerúsálẹ́mù lórí gbogbo Ísírẹ́lì. 31 Níkẹyìn, Sólómọ́nì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sin ín sí Ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀;+ Rèhóbóámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+
10 Rèhóbóámù lọ sí Ṣékémù,+ nítorí gbogbo Ísírẹ́lì ti wá sí Ṣékémù láti fi í jọba.+ 2 Gbàrà tí Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì gbọ́ (ó ṣì wà ní Íjíbítì torí ó ti sá lọ nítorí Ọba Sólómọ́nì),+ Jèróbóámù pa dà wá láti Íjíbítì. 3 Lẹ́yìn náà, wọ́n ránṣẹ́ pe Jèróbóámù, òun àti gbogbo Ísírẹ́lì sì wá bá Rèhóbóámù, wọ́n sọ pé: 4 “Bàbá rẹ mú kí àjàgà wa wúwo.+ Àmọ́ tí o bá mú kí iṣẹ́ tó nira tí bàbá rẹ fún wa rọ̀ wá lọ́rùn, tí o sì mú kí àjàgà tó wúwo* tó fi kọ́ wa lọ́rùn fúyẹ́, a ó máa sìn ọ́.”
5 Ló bá sọ fún wọn pé: “Ẹ pa dà wá bá mi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta.” Torí náà, àwọn èèyàn náà lọ.+ 6 Ọba Rèhóbóámù wá fọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbà ọkùnrin* tó bá Sólómọ́nì bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà tó wà láàyè, ó ní: “Ẹ gbà mí nímọ̀ràn, èsì wo ni ká fún àwọn èèyàn yìí?” 7 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Tí o bá ṣe dáadáa sí àwọn èèyàn yìí, tí o ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, tí o sì fún wọn ní èsì rere, ìwọ ni wọ́n á máa sìn títí lọ.”
8 Àmọ́, ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbà ọkùnrin* fún un, ó sì fọ̀rọ̀ lọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà, àmọ́ tí wọ́n ti di ẹmẹ̀wà* rẹ̀ báyìí.+ 9 Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ẹ gbà mí nímọ̀ràn, èsì wo ni ká fún àwọn èèyàn tó sọ fún mi pé, ‘Mú kí àjàgà tí bàbá rẹ fi kọ́ wa lọ́rùn fúyẹ́’?” 10 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí o máa sọ fún àwọn èèyàn tó sọ fún ọ pé, ‘Bàbá rẹ mú kí àjàgà wa wúwo, ṣùgbọ́n mú kí ó fúyẹ́ lọ́rùn wa’; ohun tí wàá sọ fún wọn ni pé, ‘Ọmọ ìka ọwọ́ mi tó kéré jù* yóò nípọn ju ìbàdí bàbá mi lọ. 11 Bàbá mi fi àjàgà tó wúwo kọ́ yín lọ́rùn, àmọ́ ńṣe ni màá fi kún àjàgà yín. Pàṣán ni bàbá mi fi nà yín, ṣùgbọ́n kòbókò oníkókó ni màá fi nà yín.’”
12 Jèróbóámù àti gbogbo àwọn èèyàn náà wá bá Rèhóbóámù ní ọjọ́ kẹta, bí ọba ṣe sọ pé: “Ẹ pa dà wá bá mi ní ọjọ́ kẹta.”+ 13 Àmọ́, ńṣe ni ọba jágbe mọ́ wọn. Bí Ọba Rèhóbóámù kò ṣe gba ìmọ̀ràn tí àwọn àgbà ọkùnrin* fún un nìyẹn. 14 Ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin fún un ló tẹ̀ lé, ó sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Màá mú kí àjàgà yín wúwo sí i, màá sì tún fi kún un. Pàṣán ni bàbá mi fi nà yín, ṣùgbọ́n kòbókò oníkókó ni màá fi nà yín.” 15 Nítorí náà, ọba ò fetí sí àwọn èèyàn náà, torí pé Ọlọ́run tòótọ́+ ló mú kí ìyípadà náà wáyé, kí ọ̀rọ̀ Jèhófà lè ṣẹ, èyí tó gbẹnu Áhíjà+ ọmọ Ṣílò sọ fún Jèróbóámù ọmọ Nébátì.
16 Ní ti gbogbo Ísírẹ́lì, torí pé ọba ò gbọ́ tiwọn, àwọn èèyàn náà fún ọba lésì pé: “Kí ló pa àwa àti Dáfídì pọ̀? A ò ní ogún kankan nínú ọmọ Jésè. Ìwọ Ísírẹ́lì, kí kálukú lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run rẹ̀. Ìwọ Dáfídì,+ máa mójú tó ilé ara rẹ!” Bí gbogbo Ísírẹ́lì ṣe pa dà sí ilé* wọn nìyẹn.+
17 Àmọ́ Rèhóbóámù ń jọba nìṣó lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé ní àwọn ìlú Júdà.+
18 Lẹ́yìn náà, Ọba Rèhóbóámù rán Hádórámù,+ ẹni tó jẹ́ olórí àwọn tí ọba ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa. Agbára káká ni Ọba Rèhóbóámù fi rọ́nà gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti sá lọ sí Jerúsálẹ́mù.+ 19 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dáfídì títí di òní yìí.
11 Nígbà tí Rèhóbóámù dé Jerúsálẹ́mù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló pe ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì+ jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) akọgun,* láti bá Ísírẹ́lì jà, kí wọ́n lè gba ìjọba pa dà fún Rèhóbóámù.+ 2 Ìgbà náà ni Jèhófà bá Ṣemáyà,+ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀, ó ní: 3 “Sọ fún Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì ọba Júdà àti gbogbo Ísírẹ́lì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì pé, 4 ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ lọ bá àwọn arákùnrin yín jà. Kí kálukú yín pa dà sí ilé rẹ̀, torí èmi ló mú kí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀.”’”+ Nítorí náà, wọ́n ṣe ohun tí Jèhófà sọ, wọ́n pa dà, wọn ò sì lọ bá Jèróbóámù jà.
5 Rèhóbóámù ń gbé Jerúsálẹ́mù, ó sì kọ́ àwọn ìlú olódi sí Júdà. 6 Ó tipa bẹ́ẹ̀ kọ́* Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ Étámì, Tékóà,+ 7 Bẹti-súrì, Sókò,+ Ádúlámù,+ 8 Gátì,+ Máréṣà, Sífù,+ 9 Ádóráímù,+ Lákíṣì, Ásékà,+ 10 Sórà, Áíjálónì+ àti Hébúrónì,+ àwọn ìlú olódi tó wà ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì. 11 Yàtọ̀ síyẹn, ó mú kí àwọn ibi olódi lágbára sí i, ó sì fi àwọn aláṣẹ sínú wọn, ó ń fún wọn ní oúnjẹ àti òróró àti wáìnì, 12 ó sì fún àwọn ìlú kọ̀ọ̀kan ní apata ńlá àti aṣóró; ó mú kí wọ́n lágbára gan-an. Ó sì ń ṣàkóso lórí Júdà àti Bẹ́ńjámínì nìṣó.
13 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tó wà ní gbogbo Ísírẹ́lì dúró tì í, wọ́n ń jáde wá láti gbogbo ìpínlẹ̀ wọn. 14 Àwọn ọmọ Léfì fi àwọn ibi ìjẹko wọn àti ohun ìní wọn sílẹ̀,+ wọ́n wá sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù, torí pé Jèróbóámù àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti lé wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà fún Jèhófà.+ 15 Jèróbóámù wá yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn ibi gíga+ àti fún àwọn ẹ̀mí èṣù+ tó rí bí ewúrẹ́* àti fún àwọn ère ọmọ màlúù tí ó ṣe.+ 16 Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n ti pinnu láti máa wá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì tẹ̀ lé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wá sí Jerúsálẹ́mù láti rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+ 17 Ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi kọ́wọ́ ti ìjọba Júdà, wọ́n sì ti Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì lẹ́yìn, wọ́n rìn ní ọ̀nà Dáfídì àti Sólómọ́nì fún ọdún mẹ́ta.
18 Nígbà náà, Rèhóbóámù fi Máhálátì ṣe aya, bàbá rẹ̀ ni Jérímótì ọmọ Dáfídì, ìyá rẹ̀ sì ni Ábíháílì ọmọ Élíábù+ ọmọ Jésè. 19 Nígbà tó yá, ó bí àwọn ọmọkùnrin fún un, àwọn ni: Jéúṣì, Ṣemaráyà àti Sáhámù. 20 Lẹ́yìn rẹ̀, ó fẹ́ Máákà ọmọ ọmọ Ábúsálómù.+ Nígbà tó yá, ó bí Ábíjà,+ Átáì, Sísà àti Ṣẹ́lómítì fún un. 21 Rèhóbóámù nífẹ̀ẹ́ Máákà ọmọ ọmọ Ábúsálómù ju gbogbo àwọn ìyàwó rẹ̀ yòókù àti àwọn wáhàrì*+ rẹ̀ lọ. Ó ní ìyàwó méjìdínlógún (18) àti ọgọ́ta (60) wáhàrì, ó sì bí ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n (28) àti ọgọ́ta (60) ọmọbìnrin. 22 Nítorí náà, Rèhóbóámù yan Ábíjà ọmọ Máákà ṣe olórí àti aṣáájú láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀, torí ó fẹ́ fi jọba. 23 Àmọ́, ó dá ọgbọ́n, ó rán lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lọ* sí gbogbo agbègbè Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti sí gbogbo àwọn ìlú olódi,+ ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun tí wọ́n nílò, ó sì fẹ́ ìyàwó púpọ̀ fún wọn.
12 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ìjọba Rèhóbóámù fìdí múlẹ̀,+ tí ó sì di alágbára, ó pa Òfin Jèhófà tì,+ òun àti gbogbo Ísírẹ́lì. 2 Ní ọdún karùn-ún Ọba Rèhóbóámù, Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù, nítorí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà. 3 Ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba (1,200) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta (60,000) àwọn agẹṣin pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí kò níye, tí wọ́n bá a wá láti Íjíbítì, ìyẹn àwọn ará Líbíà, Súkímù àti àwọn ará Etiópíà.+ 4 Ó gba àwọn ìlú olódi tó wà ní Júdà, níkẹyìn, ó dé Jerúsálẹ́mù.
5 Wòlíì Ṣemáyà+ wá sọ́dọ̀ Rèhóbóámù àti àwọn ìjòyè Júdà tí wọ́n kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù nítorí Ṣíṣákì, ó sì sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ẹ ti fi mí sílẹ̀, èmi náà ti fi yín sílẹ̀+ sí ọwọ́ Ṣíṣákì.’” 6 Àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì àti ọba wá rẹ ara wọn sílẹ̀,+ wọ́n sì sọ pé: “Olódodo ni Jèhófà.” 7 Nígbà tí Jèhófà rí i pé wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Jèhófà bá Ṣemáyà sọ̀rọ̀, ó ní: “Wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀. Mi ò ní pa wọ́n run,+ màá sì gbà wọ́n láìpẹ́. Mi ò ní tú ìbínú mi sórí Jerúsálẹ́mù látọwọ́ Ṣíṣákì. 8 Ṣùgbọ́n wọ́n á di ìránṣẹ́ rẹ̀, kí wọ́n lè mọ ìyàtọ̀ nínú sísìn mí àti sísin àwọn ọba* ilẹ̀ míì.”
9 Nítorí náà, Ṣíṣákì ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù. Ó kó àwọn ìṣúra ilé Jèhófà+ àti ìṣúra ilé* ọba. Gbogbo nǹkan pátá ló kó, títí kan àwọn apata wúrà tí Sólómọ́nì ṣe.+ 10 Nítorí náà, Ọba Rèhóbóámù ṣe àwọn apata bàbà láti fi rọ́pò wọn, ó sì fi wọ́n sí ìkáwọ́ àwọn olórí ẹ̀ṣọ́* tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba. 11 Nígbàkigbà tí ọba bá wá sí ilé Jèhófà, àwọn ẹ̀ṣọ́ á wọlé, wọ́n á sì gbé wọn, lẹ́yìn náà, wọ́n á dá wọn pa dà sí yàrá ẹ̀ṣọ́. 12 Torí pé ọba rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìbínú Jèhófà yí kúrò lórí rẹ̀,+ kò sì pa wọ́n run pátápátá.+ Yàtọ̀ síyẹn, ó rí àwọn ohun rere ní Júdà.+
13 Ọba Rèhóbóámù mú kí ipò rẹ̀ fìdí múlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, ó sì ń jọba nìṣó; ẹni ọdún mọ́kànlélógójì (41) ni Rèhóbóámù nígbà tó di ọba, ó sì fi ọdún mẹ́tàdínlógún (17) jọba ní Jerúsálẹ́mù, ìlú tí Jèhófà yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ sí. Orúkọ ìyá ọba ni Náámà, ọmọ Ámónì sì ni.+ 14 Àmọ́, ọba ṣe ohun tó burú, torí pé kò pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti wá Jèhófà.+
15 Ní ti ìtàn Rèhóbóámù, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ wòlíì Ṣemáyà+ àti ti Ídò+ aríran tó wà nínú ìtàn ìdílé? Ìgbà gbogbo ni ogun ń wáyé láàárín Rèhóbóámù àti Jèróbóámù.+ 16 Níkẹyìn, Rèhóbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì;+ Ábíjà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
13 Ní ọdún kejìdínlógún Ọba Jèróbóámù, Ábíjà jọba lórí Júdà.+ 2 Ọdún mẹ́ta ló fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Mikáyà+ ọmọ Úríélì láti Gíbíà.+ Ogun sì wáyé láàárín Ábíjà àti Jèróbóámù.+
3 Nítorí náà, Ábíjà kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lákíkanjú, tí wọ́n sì jẹ́ akọgun* lọ sójú ogun.+ Bákan náà, Jèróbóámù kó ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) àwọn ọkùnrin tó mọṣẹ́ ogun,* àwọn jagunjagun tó lákíkanjú, ó sì tò wọ́n lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti dojú kọ ọ́. 4 Ábíjà wá dúró lórí Òkè Sémáráímù tó wà ní agbègbè olókè Éfúrémù, ó sì sọ pé: “Ẹ gbọ́ mi, Jèróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì. 5 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti fún Dáfídì ní ìjọba lórí Ísírẹ́lì títí láé,+ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?*+ 6 Àmọ́ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì, ìránṣẹ́ Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì dìde, ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí olúwa rẹ̀.+ 7 Àwọn ọkùnrin aláìríkan-ṣèkan àti aláìníláárí ń kóra wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n borí Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì nígbà tí Rèhóbóámù ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, tó sì ya ojo, kò sì lè dojú kọ wọ́n.
8 “Ní báyìí, ẹ rò pé ẹ lè dojú kọ ìjọba Jèhófà tó wà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Dáfídì, torí pé ẹ pọ̀ jù wọ́n lọ, ẹ sì ní àwọn ère ọmọ màlúù wúrà tí Jèróbóámù fi ṣe àwọn ọlọ́run fún yín.+ 9 Ṣebí ẹ ti lé àwọn àlùfáà Jèhófà jáde,+ ìyẹn àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì àti àwọn ọmọ Léfì, tí ẹ sì yan àwọn àlùfáà tiyín bí àwọn èèyàn ilẹ̀ míì ti ń ṣe?+ Ẹni tó bá mú akọ ọmọ màlúù kan àti àgbò méje wá* lè di àlùfáà àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọ́run. 10 Ní tiwa, Jèhófà ni Ọlọ́run wa,+ a kò sì fi í sílẹ̀; àwọn àlùfáà wa, ìyẹn àtọmọdọ́mọ Áárónì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Jèhófà, àwọn ọmọ Léfì sì ń ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. 11 Wọ́n ń mú àwọn ẹbọ sísun rú èéfín sí Jèhófà ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́-ìrọ̀lẹ́+ pẹ̀lú tùràrí onílọ́fínńdà,+ àwọn búrẹ́dì onípele*+ sì wà lórí tábìlì ògidì wúrà, wọ́n máa ń tan ọ̀pá fìtílà wúrà+ àti àwọn fìtílà rẹ̀ ní alaalẹ́,+ nítorí pé à ń ṣe ojúṣe wa fún Jèhófà Ọlọ́run wa; àmọ́ ẹ̀yin ti fi í sílẹ̀. 12 Ẹ wò ó! Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú wa, ó ń darí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ sì wà níbí láti máa fun kàkàkí láti fi pe ogun sí yín. Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ má ṣe bá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín jà, torí ẹ ò ní ṣàṣeyọrí.”+
13 Àmọ́ Jèróbóámù rán àwọn kan láti lọ lúgọ kí wọ́n lè yọ sí wọn látẹ̀yìn, ó wá di pé wọ́n wà níwájú Júdà, àwọn tó lúgọ sì wà lẹ́yìn wọn. 14 Nígbà tí àwọn èèyàn Júdà bojú wẹ̀yìn, wọ́n rí i pé ogun ń bọ̀ níwájú, ogun ń bọ̀ lẹ́yìn. Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà,+ àwọn àlùfáà sì ń fun kàkàkí kíkankíkan. 15 Àwọn èèyàn Júdà bú sẹ́kún nítorí ogun, nígbà tí àwọn èèyàn Júdà kígbe ogun, Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ́gun Jèróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì níwájú Ábíjà àti Júdà. 16 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sá níwájú Júdà, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé Júdà lọ́wọ́. 17 Ábíjà àti àwọn èèyàn rẹ̀ pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ, òkú àwọn tí wọ́n pa lára Ísírẹ́lì sì wà nílẹ̀ bẹẹrẹbẹ, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000) àwọn ọkùnrin tó mọṣẹ́ ogun.* 18 Bí a ṣe rẹ àwọn èèyàn Ísírẹ́lì wálẹ̀ ní àkókò náà nìyẹn, àwọn èèyàn Júdà sì borí wọn torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé* Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+ 19 Ábíjà ń lépa Jèróbóámù nìṣó, ó sì gba àwọn ìlú lọ́wọ́ rẹ̀, Bẹ́tẹ́lì+ pẹ̀lú àwọn àrọko rẹ̀,* Jẹ́ṣánà pẹ̀lú àwọn àrọko rẹ̀ àti Éfúrénì+ pẹ̀lú àwọn àrọko rẹ̀. 20 Jèróbóámù kò tún lágbára mọ́ nígbà ayé Ábíjà; níkẹyìn, Jèhófà kọ lù ú, ó sì kú.+
21 Àmọ́ Ábíjà ń lágbára sí i. Nígbà tó yá, ó fẹ́ ìyàwó mẹ́rìnlá (14),+ ó sì bí ọmọkùnrin méjìlélógún (22) àti ọmọbìnrin mẹ́rìndínlógún (16). 22 Ìyókù ìtàn Ábíjà, àwọn ohun tó ṣe àti àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà lákọsílẹ̀ nínú àwọn ìwé* wòlíì Ídò.+
14 Níkẹyìn, Ábíjà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sin ín sí Ìlú Dáfídì;+ Ásà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀. Nígbà ayé rẹ̀, ilẹ̀ náà ní àlàáfíà fún ọdún mẹ́wàá.
2 Ásà ṣe ohun tó dára tó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. 3 Ó mú àwọn pẹpẹ àjèjì+ àti àwọn ibi gíga kúrò, ó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́,+ ó sì gé àwọn òpó òrìṣà lulẹ̀.*+ 4 Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ fún Júdà pé kí wọ́n wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, kí wọ́n sì máa pa Òfin àti àṣẹ rẹ̀ mọ́. 5 Torí náà, ó mú àwọn ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tùràrí kúrò ní gbogbo àwọn ìlú Júdà,+ ìjọba náà sì wà láìsí ìyọlẹ́nu lábẹ́ àbójútó rẹ̀. 6 Ó kọ́ àwọn ìlú olódi sí Júdà,+ nítorí pé kò sí ìyọlẹ́nu ní ilẹ̀ náà, wọn kò sì bá a jagun ní àwọn ọdún yẹn, torí Jèhófà fún un ní ìsinmi.+ 7 Ó sọ fún Júdà pé: “Ẹ jẹ́ ká kọ́ àwọn ìlú yìí, ká sì mọ ògiri àti àwọn ilé gogoro+ yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ẹnubodè* àti àwọn ọ̀pá ìdábùú. Nítorí ilẹ̀ náà ṣì wà ní ìkáwọ́ wa, torí a ti wá Jèhófà Ọlọ́run wa. A ti wá a, ó sì ti fún wa ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó yí wa ká.” Torí náà, wọ́n parí àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́.+
8 Ásà ní àwọn ọmọ ogun tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) ọkùnrin láti Júdà, apata ńlá àti aṣóró wà lọ́wọ́ wọn. Ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) jagunjagun tó lákíkanjú láti inú Bẹ́ńjámínì ló ń gbé asà,* tí wọ́n sì ní ọfà lọ́wọ́.*+
9 Lẹ́yìn náà, Síírà ará Etiópíà wá gbéjà kò wọ́n pẹ̀lú ọmọ ogun tó jẹ́ mílíọ̀nù kan (1,000,000) ọkùnrin àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) kẹ̀kẹ́ ẹṣin.+ Nígbà tó dé Máréṣà,+ 10 Ásà jáde lọ gbéjà kò ó, wọ́n sì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun ní Àfonífojì Séfátà ní Máréṣà. 11 Ásà wá ké pe Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+ ó ní: “Jèhófà, kò jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ bóyá àwọn tí o fẹ́ ràn lọ́wọ́ pọ̀ tàbí wọn ò lágbára. + Ràn wá lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé,*+ a wá ní orúkọ rẹ láti dojú kọ ọ̀pọ̀ èèyàn yìí.+ Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run wa. Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú borí rẹ.”+
12 Torí náà, Jèhófà ṣẹ́gun àwọn ará Etiópíà níwájú Ásà àti níwájú Júdà, àwọn ará Etiópíà sì sá lọ.+ 13 Ásà àti àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ń lé wọn lọ títí dé Gérárì,+ àwọn ará Etiópíà sì ń ṣubú títí kò fi sí ìkankan lára wọn tó wà láàyè, torí pé Jèhófà àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n kó ẹrù ogun tó pọ̀ gan-an. 14 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n kọ lu gbogbo àwọn ìlú tó yí Gérárì ká, nítorí Jèhófà ti kó jìnnìjìnnì bá wọn; wọ́n sì kó ẹrù gbogbo àwọn ìlú náà, nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà níbẹ̀ tí wọ́n lè kó. 15 Wọ́n tún kọ lu àgọ́ àwọn tó ní ẹran ọ̀sìn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ agbo ẹran àti ràkúnmí, lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù.
15 Nígbà náà, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé Asaráyà ọmọ Ódédì. 2 Nítorí náà, ó lọ bá Ásà, ó sì sọ fún un pé: “Gbọ́ mi, ìwọ Ásà àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì! Jèhófà á máa wà pẹ̀lú yín tí ẹ ò bá ti fi í sílẹ̀;+ tí ẹ bá sì wá a, á jẹ́ kí ẹ rí òun,+ àmọ́ tí ẹ bá fi í sílẹ̀, á fi yín sílẹ̀.+ 3 Ó ti pẹ́ gan-an tí* Ísírẹ́lì ti wà láìní Ọlọ́run tòótọ́, tí wọn ò ní àlùfáà tó ń kọ́ni, tí wọn ò sì ní òfin.+ 4 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì torí pé wọ́n wà nínú wàhálà, tí wọ́n sì wá a, ó jẹ́ kí wọ́n rí òun.+ 5 Ní àkókò yẹn, ewú wà fún àwọn tó ń rìnrìn àjò,* torí pé ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé àwọn ilẹ̀ náà kò balẹ̀ rárá. 6 Orílẹ̀-èdè ń ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè, ìlú kan sì ń ṣẹ́gun ìlú míì, nítorí pé Ọlọ́run fi oríṣiríṣi wàhálà kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+ 7 Àmọ́ ní tiyín, ẹ jẹ́ alágbára, ẹ má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá yín,*+ nítorí pé èrè wà fún iṣẹ́ yín.”
8 Gbàrà tí Ásà gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí àti àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Ódédì, ó mọ́kàn le, ó sì mú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Júdà+ àti Bẹ́ńjámínì àti ní àwọn ìlú tó gbà ní agbègbè olókè Éfúrémù, ó tún pẹpẹ Jèhófà tó wà níwájú ibi tí wọ́n ń gbà wọ* ilé Jèhófà mọ.+ 9 Ó kó gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ pẹ̀lú àwọn àjèjì tó wà pẹ̀lú wọn tí wọ́n wá láti Éfúrémù àti Mánásè àti Síméónì,+ torí ọ̀pọ̀ wọn ló sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n rí i pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. 10 Torí náà, wọ́n kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù ní oṣù kẹta ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìjọba Ásà. 11 Lọ́jọ́ yẹn, wọ́n fi ọgọ́rùn-ún méje (700) màlúù àti ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àgùntàn rúbọ sí Jèhófà látinú ẹrù ogun tí wọ́n kó dé. 12 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n dá májẹ̀mú pé àwọn á fi gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo ara*+ wọn wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn. 13 Wọ́n á pa ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ì báà jẹ́ ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, ọkùnrin tàbí obìnrin.+ 14 Torí náà, wọ́n búra fún Jèhófà ní ohùn rara pẹ̀lú igbe ìdùnnú àti kàkàkí àti ìwo. 15 Inú gbogbo Júdà dùn sí ìbúra náà, nítorí pé gbogbo ọkàn wọn ni wọ́n fi búra àti pé wọ́n fi ìtara wá a, ó sì jẹ́ kí wọ́n rí òun.+ Jèhófà sì ń fún wọn ní ìsinmi ní ibi gbogbo.+
16 Ọba Ásà tiẹ̀ tún yọ Máákà+ ìyá rẹ̀ àgbà kúrò ní ipò ìyá ọba,* torí pé ó ṣe òrìṣà ẹ̀gbin tí wọ́n fi ń jọ́sìn òpó òrìṣà.*+ Ásà gé òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀ lulẹ̀, ó rún un wómúwómú, ó sì sun ún ní Àfonífojì Kídírónì.+ 17 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò+ ní Ísírẹ́lì. + Síbẹ̀, Ásà fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Ọlọ́run* ní gbogbo ọjọ́ ayé* rẹ̀.+ 18 Ó kó àwọn ohun tí òun àti bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́, ìyẹn fàdákà, wúrà àti àwọn ohun èlò míì.+ 19 Kò sí ogun títí di ọdún karùndínlógójì ìjọba Ásà.+
16 Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìjọba Ásà, Bááṣà+ ọba Ísírẹ́lì wá dojú kọ Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́* Rámà,+ kí ẹnikẹ́ni má bàa jáde tàbí kí ó wọlé sọ́dọ̀* Ásà ọba Júdà.+ 2 Ni Ásà bá kó fàdákà àti wúrà jáde látinú àwọn ibi ìṣúra ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Bẹni-hádádì ọba Síríà+ tó ń gbé ní Damásíkù, ó sọ pé: 3 “Àdéhùn* kan wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín bàbá mi àti bàbá rẹ. Mo fi fàdákà àti wúrà ránṣẹ́ sí ọ. Wò ó, lọ yẹ àdéhùn* tí o bá Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ṣe, kó lè pa dà lẹ́yìn mi.”
4 Bẹni-hádádì ṣe ohun tí Ọba Ásà sọ, ó rán àwọn olórí ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko àwọn ìlú Ísírẹ́lì, wọ́n sì ṣá Íjónì,+ Dánì + àti Ebẹli-máímù balẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ibi tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí ní àwọn ìlú Náfútálì.+ 5 Nígbà tí Bááṣà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló jáwọ́ nínú kíkọ́* Rámà, ó sì pa iṣẹ́ tó ń ṣe níbẹ̀ tì. 6 Ọba Ásà wá kó gbogbo Júdà jọ, wọ́n kó àwọn òkúta àti ẹ̀là gẹdú tó wà ní Rámà,+ tí Bááṣà fi ń kọ́lé,+ ó sì fi wọ́n kọ́* Gébà+ àti Mísípà.+
7 Ní àkókò yẹn, Hánáánì+ aríran wá bá Ásà ọba Júdà, ó sì sọ fún un pé: “Nítorí o gbẹ́kẹ̀ lé* ọba Síríà, tí o kò sì gbẹ́kẹ̀ lé* Jèhófà Ọlọ́run rẹ, àwọn ọmọ ogun ọba Síríà ti bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́.+ 8 Ṣebí àwọn ará Etiópíà àti àwọn ará Líbíà ní àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ rẹpẹtẹ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú àwọn agẹṣin? Àmọ́ torí pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.+ 9 Nítorí ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé+ láti fi agbára* rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.+ O ti hùwà òmùgọ̀ lórí ọ̀ràn yìí; láti ìsinsìnyí lọ, ogun yóò máa jà ọ́.”+
10 Àmọ́, inú bí Ásà sí aríran náà, ó sì fi í sẹ́wọ̀n,* torí ohun tó sọ mú kí Ásà gbaná jẹ. Ní àkókò yẹn kan náà, Ásà bẹ̀rẹ̀ sí í fìyà jẹ àwọn kan lára àwọn èèyàn náà. 11 Ní ti ìtàn Ásà, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì.+
12 Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba Ásà, àrùn kan mú un ní ẹsẹ̀, ó sì di àìsàn ńlá sí i lára; síbẹ̀ nínú àìsàn tó wà, kò yíjú sí Jèhófà, àwọn oníṣègùn ló yíjú sí. 13 Níkẹyìn, Ásà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ ó kú ní ọdún kọkànlélógójì ìjọba rẹ̀. 14 Nítorí náà, wọ́n sin ín sí ibi ìsìnkú rẹ̀ tó lọ́lá, èyí tó gbẹ́ fún ara rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì;+ wọ́n sì tẹ́ ẹ sórí àga ìgbókùú tí wọ́n ti fi òróró básámù sí lára àti oríṣiríṣi èròjà tí a pò mọ́ àkànṣe òróró ìpara.+ Síwájú sí i, wọ́n ṣe ìfinásun* tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nítorí rẹ̀ nígbà ìsìnkú rẹ̀.
17 Jèhóṣáfátì ọmọ rẹ̀ + jọba ní ipò rẹ̀, ó sì mú kí ipò rẹ̀ fìdí múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì. 2 Ó kó àwọn ológun sí gbogbo ìlú olódi Júdà, ó sì fi àwọn ọmọ ogun sí ilẹ̀ Júdà àti sínú àwọn ìlú Éfúrémù tí Ásà bàbá rẹ̀ gbà.+ 3 Jèhófà wà pẹ̀lú Jèhóṣáfátì nítorí pé ó rìn ní àwọn ọ̀nà tí Dáfídì+ baba ńlá rẹ̀ rìn nígbà àtijọ́, kò sì wá àwọn Báálì. 4 Ó wá Ọlọ́run bàbá rẹ̀,+ ó ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́,* kò sì hu ìwà tí Ísírẹ́lì ń hù.+ 5 Jèhófà fìdí ìjọba náà múlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀;+ gbogbo Júdà ń mú ẹ̀bùn wá fún Jèhóṣáfátì, ó sì ní ọrọ̀ àti ògo tó pọ̀ gan-an.+ 6 Ó ní ìgboyà láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà, kódà ó mú àwọn ibi gíga+ àti àwọn òpó òrìṣà*+ kúrò ní Júdà.
7 Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó ránṣẹ́ pe àwọn ìjòyè rẹ̀, ìyẹn Bẹni-háílì, Ọbadáyà, Sekaráyà, Nétánélì àti Mikáyà, ó ní kí wọ́n lọ máa kọ́ni ní àwọn ìlú Júdà. 8 Àwọn ọmọ Léfì wà pẹ̀lú wọn, àwọn ni: Ṣemáyà, Netanáyà, Sebadáyà, Ásáhélì, Ṣẹ́mírámótì, Jèhónátánì, Ádóníjà, Tóbíjà àti Tobu-ádóníjà, àwọn àlùfáà+ tó wà pẹ̀lú wọn ni Élíṣámà àti Jèhórámù. 9 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni ní Júdà, wọ́n mú ìwé Òfin Jèhófà dání,+ wọ́n sì lọ yí ká gbogbo àwọn ìlú Júdà, wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn.
10 Ẹ̀rù Jèhófà ba gbogbo ìjọba àwọn ilẹ̀ tó yí Júdà ká, wọn ò sì bá Jèhóṣáfátì jà. 11 Àwọn Filísínì ń mú ẹ̀bùn àti owó wá fún Jèhóṣáfátì, wọ́n fi ń san ìṣákọ́lẹ̀.* Àwọn ará Arébíà mú ẹgbẹ̀rún méje ó lé ọgọ́rùn-ún méje (7,700) àgbò àti ẹgbẹ̀rún méje ó lé ọgọ́rùn-ún méje (7,700) òbúkọ wá fún un látinú agbo ẹran wọn.
12 Agbára Jèhóṣáfátì ń pọ̀ sí i,+ ó sì ń kọ́ àwọn ibi olódi+ àti àwọn ìlú tó ń kó nǹkan pa mọ́ sí+ ní Júdà. 13 Ó gbé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe ní àwọn ìlú Júdà, ó sì ní àwọn ọmọ ogun, àwọn jagunjagun tó lákíkanjú, ní Jerúsálẹ́mù. 14 Wọ́n pín wọn sí agbo ilé àwọn bàbá wọn: nínú àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún látinú Júdà, àkọ́kọ́ ni Ádínáhì olórí, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) jagunjagun tó lákíkanjú sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 15 Ẹni tó wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀ ni Jèhóhánánì olórí, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 16 Ẹni tó tún wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀ ni Amasáyà ọmọ Síkírì, ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) jagunjagun tó lákíkanjú sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 17 Bákan náà, Élíádà látinú Bẹ́ńjámínì,+ ó jẹ́ jagunjagun tó lákíkanjú, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) ọkùnrin tí wọ́n ní ọfà* lọ́wọ́, tí wọ́n sì gbé apata dání wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 18 Ẹni tó tún wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀ ni Jèhósábádì, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) ọkùnrin tí wọ́n ti gbára dì láti wọṣẹ́ ológun sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 19 Gbogbo wọn ló ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba, yàtọ̀ sí àwọn tí ọba fi sínú àwọn ìlú olódi ní gbogbo Júdà.+
18 Jèhóṣáfátì ní ọrọ̀ àti ògo tó pọ̀ gan-an,+ àmọ́ ó bá Áhábù+ dána. 2 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ó lọ sọ́dọ̀ Áhábù ní Samáríà,+ Áhábù sì pa ọ̀pọ̀ àgùntàn àti màlúù* fún òun àti àwọn tó bá a wá. Ó wá rọ̀ ọ́* pé kó tẹ̀ lé òun lọ gbéjà ko Ramoti-gílíádì.+ 3 Áhábù ọba Ísírẹ́lì sì sọ fún Jèhóṣáfátì ọba Júdà pé: “Ṣé wàá tẹ̀ lé mi lọ sí Ramoti-gílíádì?” Ó dá a lóhùn pé: “Ìkan náà ni èmi àti ìwọ, ìkan náà sì ni àwọn èèyàn mi àti àwọn èèyàn rẹ, a ó tì ọ́ lẹ́yìn nínú ogun náà.”
4 Àmọ́, Jèhóṣáfátì sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Jọ̀wọ́, kọ́kọ́ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà.”+ 5 Torí náà, ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì jọ, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin, ó sì bi wọ́n pé: “Ṣé ká lọ bá Ramoti-gílíádì jà tàbí ká má lọ?” Wọ́n dá a lóhùn pé: “Lọ, Ọlọ́run tòótọ́ yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”
6 Jèhóṣáfátì wá sọ pé: “Ṣé kò sí wòlíì Jèhófà níbí ni?+ Ẹ jẹ́ ká tún wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀.”+ 7 Ni ọba Ísírẹ́lì bá sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ọkùnrin kan ṣì wà+ tí a lè ní kó bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà; ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀, nítorí kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi ibi ṣáá.+ Mikáyà ni orúkọ rẹ̀, ọmọ Ímílà ni.” Síbẹ̀, Jèhóṣáfátì sọ pé: “Kí ọba má sọ bẹ́ẹ̀.”
8 Torí náà, ọba Ísírẹ́lì pe òṣìṣẹ́ ààfin kan, ó sì sọ fún un pé: “Lọ pe Mikáyà ọmọ Ímílà wá kíákíá.”+ 9 Lásìkò náà, ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà wà ní ìjókòó, kálukú lórí ìtẹ́ rẹ̀, wọ́n wọ ẹ̀wù oyè; wọ́n jókòó sí ibi ìpakà tó wà ní àtiwọ ẹnubodè Samáríà, gbogbo àwọn wòlíì sì ń sọ tẹ́lẹ̀ níwájú wọn. 10 Ìgbà náà ni Sedekáyà ọmọ Kénáánà ṣe àwọn ìwo irin fún ara rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ohun tí o máa fi kan* àwọn ará Síríà pa nìyí títí wàá fi pa wọ́n run.’” 11 Ohun kan náà ni gbogbo àwọn wòlíì tó kù ń sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n ń sọ pé: “Lọ sí Ramoti-gílíádì, wàá ṣẹ́gun;+ Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”
12 Òjíṣẹ́ tó lọ pe Mikáyà sọ fún un pé: “Wò ó! Ohun rere ni àwọn wòlíì ń sọ fún ọba, ọ̀rọ̀ wọn kò ta kora. Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ yàtọ̀ sí tiwọn,+ kí o sì sọ ohun rere.”+ 13 Ṣùgbọ́n Mikáyà sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ohun tí Ọlọ́run mi bá sọ fún mi ni màá sọ.”+ 14 Lẹ́yìn náà, ó wọlé sọ́dọ̀ ọba, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Mikáyà, ṣé ká lọ bá Ramoti-gílíádì jà àbí ká má lọ?” Lójú ẹsẹ̀, ó fèsì pé: “Lọ, wàá ṣẹ́gun; a ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.” 15 Ni ọba bá sọ fún un pé: “Ìgbà mélòó ni màá ní kí o búra pé òótọ́ lo máa sọ fún mi ní orúkọ Jèhófà?” 16 Nítorí náà, ó sọ pé: “Mo rí i tí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tú ká lórí àwọn òkè, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.+ Jèhófà sọ pé: ‘Àwọn yìí kò ní ọ̀gá. Kí kálukú pa dà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’”
17 Nígbà náà, ọba Ísírẹ́lì sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé, ‘Kò ní sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi, àfi ibi’?”+
18 Mikáyà bá sọ pé: “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: Mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀,+ gbogbo ọmọ ogun ọ̀run+ sì dúró lápá ọ̀tún rẹ̀ àti lápá òsì rẹ̀.+ 19 Jèhófà sì sọ pé, ‘Ta ló máa tan Áhábù ọba Ísírẹ́lì, kí ó lè lọ kí ó sì kú ní Ramoti-gílíádì?’ Ẹni tibí ń sọ báyìí, ẹni tọ̀hún sì ń sọ nǹkan míì. 20 Ni ẹ̀mí*+ kan bá jáde wá, ó dúró níwájú Jèhófà, ó sì sọ pé, ‘Màá tàn án.’ Jèhófà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘Báwo lo ṣe máa ṣe é?’ 21 Ó dáhùn pé, ‘Màá jáde lọ, màá sì di ẹ̀mí tó ń tanni jẹ ní ẹnu gbogbo wòlíì rẹ̀.’ Torí náà, ó sọ pé, ‘O máa tàn án, kódà, wàá ṣe àṣeyọrí. Lọ, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ 22 Wò ó, Jèhófà ti fi ẹ̀mí tó ń tanni jẹ sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ yìí,+ àmọ́ àjálù ni Jèhófà sọ pé ó máa bá ọ.”
23 Sedekáyà+ ọmọ Kénáánà wá sún mọ́ tòsí, ó sì gbá Mikáyà + létí,+ ó sọ pé: “Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Jèhófà gbà kúrò lára mi tó fi wá bá ọ sọ̀rọ̀?”+ 24 Mikáyà dá a lóhùn pé: “Wò ó! Wàá rí ọ̀nà tó gbà lọ́jọ́ tí o máa lọ sá pa mọ́ sí yàrá inú lọ́hùn-ún.” 25 Ìgbà náà ni ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Ẹ mú Mikáyà, kí ẹ sì fà á lé ọwọ́ Ámọ́nì olórí ìlú àti Jóáṣì ọmọ ọba. 26 Ẹ sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí ọba sọ nìyí: “Ẹ fi ọ̀gbẹ́ni yìí sínú ẹ̀wọ̀n,+ kí ẹ sì máa fún un ní oúnjẹ díẹ̀ àti omi díẹ̀, títí màá fi dé ní àlàáfíà.”’” 27 Àmọ́ Mikáyà sọ pé: “Tí o bá pa dà ní àlàáfíà, á jẹ́ pé Jèhófà kò bá mi sọ̀rọ̀.”+ Ó tún sọ pé: “Ẹ fọkàn sí i o, gbogbo ẹ̀yin èèyàn.”
28 Ni ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà bá lọ sí Ramoti-gílíádì.+ 29 Ọba Ísírẹ́lì sì sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Màá para dà, màá sì lọ sójú ogun, ṣùgbọ́n ní tìrẹ, wọ ẹ̀wù oyè rẹ.” Torí náà, ọba Ísírẹ́lì para dà, wọ́n sì bọ́ sójú ogun. 30 Ọba Síríà ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà, ì báà jẹ́ ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, àfi ọba Ísírẹ́lì.” 31 Gbàrà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí Jèhóṣáfátì, wọ́n sọ lọ́kàn ara wọn pé: “Ọba Ísírẹ́lì nìyí.” Nítorí náà, wọ́n yíjú sí i láti bá a jà; Jèhóṣáfátì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́,+ Jèhófà ràn án lọ́wọ́, Ọlọ́run sì darí wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 32 Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí i pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n pa dà lẹ́yìn rẹ̀.
33 Àmọ́, ọkùnrin kan ṣàdédé ta ọfà rẹ̀,* ó sì ba ọba Ísírẹ́lì láàárín ibi tí ẹ̀wù irin rẹ̀ ti so pọ̀. Torí náà, ọba sọ fún ẹni tó ń wa kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pé: “Yí pa dà, kí o sì gbé mi jáde kúrò lójú ogun,* nítorí mo ti fara gbọgbẹ́ gan-an.”+ 34 Ìjà náà le gan-an jálẹ̀ ọjọ́ yẹn, kódà wọ́n ní láti gbé ọba Ísírẹ́lì nàró nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ará Síríà jà títí di ìrọ̀lẹ́; ó sì kú nígbà tí oòrùn wọ̀.+
19 Lẹ́yìn náà, Jèhóṣáfátì ọba Júdà pa dà sí ilé* rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù láìséwu.*+ 2 Jéhù+ ọmọ Hánáánì+ aríran jáde lọ bá Ọba Jèhóṣáfátì, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé èèyàn burúkú ló yẹ kí o máa ràn lọ́wọ́,+ ṣé àwọn tó kórìíra Jèhófà ló sì yẹ kí o nífẹ̀ẹ́?+ Nítorí èyí, ìbínú Jèhófà ru sí ọ. 3 Síbẹ̀, àwọn ohun rere kan wà tí a rí nínú rẹ,+ nítorí o ti mú àwọn òpó òrìṣà* kúrò ní ilẹ̀ yìí, o sì ti múra ọkàn rẹ sílẹ̀* láti wá Ọlọ́run tòótọ́.”+
4 Jèhóṣáfátì ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, ó sì tún jáde lọ sáàárín àwọn èèyàn náà láti Bíá-ṣébà dé agbègbè olókè Éfúrémù,+ kó lè mú wọn pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+ 5 Ó tún yan àwọn onídàájọ́ káàkiri ilẹ̀ náà ní gbogbo àwọn ìlú olódi Júdà, láti ìlú dé ìlú.+ 6 Ó sọ fún àwọn onídàájọ́ náà pé: “Ẹ fiyè sí ohun tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí kì í ṣe èèyàn lẹ̀ ń ṣojú fún tí ẹ bá ń dájọ́, Jèhófà ni, ó sì wà pẹ̀lú yín nígbà tí ẹ bá ń ṣe ìdájọ́.+ 7 Ẹ jẹ́ kí ìbẹ̀rù Jèhófà wà lọ́kàn yín.+ Ẹ máa kíyè sára nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí pé kò sí àìṣẹ̀tọ́,+ kò sí ojúsàájú,+ bẹ́ẹ̀ ni kò sí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.”+
8 Ní Jerúsálẹ́mù, Jèhóṣáfátì tún yan àwọn kan lára àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn olórí agbo ilé Ísírẹ́lì láti máa ṣe onídàájọ́ fún Jèhófà àti láti máa yanjú àwọn ẹjọ́ fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.+ 9 Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ máa ṣe láti fi hàn pé ẹ bẹ̀rù Jèhófà nìyí, kí ẹ sì ṣe é pẹ̀lú ìṣòtítọ́ àti gbogbo ọkàn yín:* 10 Nígbà tí àwọn arákùnrin yín bá wá láti ìlú wọn, tí wọ́n gbé ẹjọ́ tó jẹ mọ́ ìtàjẹ̀sílẹ̀+ tàbí ìbéèrè nípa òfin, àṣẹ, àwọn ìlànà tàbí àwọn ìdájọ́ wá, kí ẹ kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má bàa jẹ̀bi lọ́dọ̀ Jèhófà; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìbínú rẹ̀ máa wá sórí ẹ̀yin àti àwọn arákùnrin yín. Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí kí ẹ má bàa jẹ̀bi. 11 Amaráyà olórí àlùfáà rèé, òun ni olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ti Jèhófà.+ Sebadáyà ọmọ Íṣímáẹ́lì ni olórí ilé Júdà nínú gbogbo ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ti ọba. Àwọn ọmọ Léfì yóò sì jẹ́ aláṣẹ yín. Ẹ jẹ́ alágbára, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀, kí Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn tó ń ṣe rere.”*+
20 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Móábù+ àti àwọn ọmọ Ámónì+ pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn Ámónímù* wá láti bá Jèhóṣáfátì jà. 2 Àwọn kan wá sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ti wá láti agbègbè òkun,* láti Édómù,+ kí wọ́n lè bá ọ jà, wọ́n sì wà ní Hasasoni-támárì, ìyẹn Ẹ́ń-gédì.”+ 3 Ni ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ba Jèhóṣáfátì, ó sì pinnu láti wá* Jèhófà. + Nítorí náà, ó kéde ààwẹ̀ fún gbogbo Júdà. 4 Àwọn èèyàn Júdà wá kóra jọ láti wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà;+ wọ́n wá láti gbogbo àwọn ìlú Júdà kí wọ́n lè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà.
5 Nígbà náà, Jèhóṣáfátì dìde láàárín ìjọ Júdà àti ti Jerúsálẹ́mù nínú ilé Jèhófà níwájú àgbàlá tuntun, 6 ó sì sọ pé:
“Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ṣebí ìwọ ni Ọlọ́run ní ọ̀run;+ ṣebí ìwọ lò ń ṣàkóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè?+ Ọwọ́ rẹ ni agbára àti okun wà, kò sì sẹ́ni tó lè dojú kọ ọ́.+ 7 Ìwọ Ọlọ́run wa, ṣebí ìwọ lo lé àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí kúrò níwájú àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, tí o sì wá fún àtọmọdọ́mọ* ọ̀rẹ́ rẹ Ábúráhámù pé kí ó jẹ́ ohun ìní wọn títí lọ?+ 8 Wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà, wọ́n sì kọ́ ibi mímọ́ síbẹ̀ fún ọ, èyí tó wà fún orúkọ rẹ,+ wọ́n sọ pé, 9 ‘Tí àjálù bá dé bá wa, ì báà jẹ́ idà tàbí ìdájọ́ tí kò bára dé tàbí àjàkálẹ̀ àrùn tàbí ìyàn, jẹ́ ká dúró níwájú ilé yìí àti níwájú rẹ (nítorí orúkọ rẹ wà nínú ilé yìí),+ ká sì ké pè ọ́ pé kí o ràn wá lọ́wọ́ nínú wàhálà wa, kí o gbọ́ kí o sì gbà wá.’+ 10 Ní báyìí, àwọn èèyàn Ámónì àti Móábù pẹ̀lú agbègbè olókè Séírì+ ti wà níbí, àwọn tí o kò yọ̀ǹda fún Ísírẹ́lì láti gba ilẹ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti ilẹ̀ Íjíbítì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn ò sì pa wọ́n rẹ́.+ 11 Ní báyìí, ohun tí wọ́n fẹ́ fi san án fún wa ni pé kí wọ́n wá lé wa jáde kúrò lórí ohun ìní rẹ tí o fún wa láti jogún. + 12 Ọlọ́run wa, ṣé o ò ní dá wọn lẹ́jọ́ ni?+ Nítorí a ò ní agbára kankan níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń bọ̀ wá bá wa yìí; a ò sì mọ ohun tó yẹ ká ṣe,+ àmọ́ ojú rẹ là ń wò.”+
13 Lákòókò yìí, gbogbo àwọn tó wá láti Júdà dúró níwájú Jèhófà, títí kan àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ* wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn kéékèèké.
14 Ní àárín ìjọ náà, ẹ̀mí Jèhófà bà lé Jáhásíẹ́lì ọmọ Sekaráyà ọmọ Bẹnáyà ọmọ Jéélì ọmọ Matanáyà ọmọ Léfì látinú àwọn ọmọ Ásáfù. 15 Ó sọ pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo Júdà àti ẹ̀yin tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti Ọba Jèhóṣáfátì! Ohun tí Jèhófà sọ fún yín nìyí, ‘Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn yìí, torí ìjà náà kì í ṣe tiyín, ti Ọlọ́run ni.+ 16 Ní ọ̀la, ẹ lọ dojú kọ wọ́n. Ọ̀nà Sísì ni wọ́n máa gbà wá, ẹ ó sì rí wọn ní òpin àfonífojì tó wà níwájú aginjù Jérúélì. 17 Kò ní sídìí fún yín láti ja ogun yìí. Ẹ dúró sáyè yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́,+ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà lórí yín.*+ Ìwọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù, ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà.+ Ní ọ̀la, ẹ jáde sí wọn, Jèhófà á sì wà pẹ̀lú yín.’”+
18 Ní kíá, Jèhóṣáfátì dojú bolẹ̀, gbogbo Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù sì wólẹ̀ níwájú Jèhófà láti jọ́sìn Jèhófà. 19 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn ọmọ Kóhátì+ àti àwọn ọmọ Kórà dìde láti fi ohùn tó ròkè yin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+
20 Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì lọ sí aginjù Tékóà.+ Bí wọ́n ṣe ń lọ, Jèhóṣáfátì dúró, ó sì sọ pé: “Ẹ gbọ́ mi, Júdà àti ẹ̀yin tó ń gbé Jerúsálẹ́mù! Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run yín kí ẹ lè dúró gbọn-in gbọn-in.* Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀,+ ẹ ó sì ṣàṣeyọrí.”
21 Lẹ́yìn tó fọ̀rọ̀ lọ àwọn èèyàn náà, ó yan àwọn kan láti máa kọrin,+ kí wọ́n sì máa yin Jèhófà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ mímọ́ bí wọ́n ṣe ń lọ níwájú àwọn ọkùnrin tó dìhámọ́ra, wọ́n ní: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”+
22 Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin ìyìn tìdùnnútìdùnnú, Jèhófà mú kí àwọn kan lúgọ de àwọn èèyàn Ámónì, Móábù àti agbègbè olókè Séírì tí wọ́n ń ya bọ̀ ní Júdà, wọ́n sì ń ṣá ara wọn balẹ̀.+ 23 Àwọn ọmọ Ámónì àti àwọn ọmọ Móábù dojú kọ àwọn tó ń gbé agbègbè olókè Séírì+ láti pa wọ́n run pátápátá; nígbà tí wọ́n yanjú àwọn tó ń gbé Séírì tán, wọ́n dojú ìjà kọ ara wọn, wọ́n sì pa ara wọn.+
24 Àmọ́ nígbà tí àwọn èèyàn Júdà dé ilé ìṣọ́ tó wà ní aginjù,+ tí wọ́n sì bojú wo àwọn èèyàn náà, wọ́n rí òkú wọn nílẹ̀ bẹẹrẹbẹ;+ kò sẹ́ni tó yè bọ́. 25 Nítorí náà, Jèhóṣáfátì àti àwọn èèyàn rẹ̀ wá kó ẹrù ogun láti ara àwọn èèyàn náà, wọ́n sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù, aṣọ àti àwọn ohun èlò tó fani mọ́ra, ohun tí wọ́n bọ́ lára wọn pọ̀ débi pé wọn ò lè kó wọn tán.+ Ọjọ́ mẹ́ta ló gbà kí wọ́n tó lè kó àwọn ẹrù ogun náà, nítorí ó pọ̀ gan-an. 26 Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n péjọ sí Àfonífojì* Bérákà, ibẹ̀ ni wọ́n ti yin* Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Àfonífojì Bérákà*+ títí di òní.
27 Lẹ́yìn náà, Jèhóṣáfátì darí gbogbo èèyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù pa dà sí Jerúsálẹ́mù tìdùnnútìdùnnú, nítorí Jèhófà ti mú kí wọ́n yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn.+ 28 Torí náà, wọ́n dé sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ pẹ̀lú kàkàkí, + wọ́n sì lọ sí ilé Jèhófà.+ 29 Ẹ̀rù Ọlọ́run ba gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jèhófà ti bá àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì jà.+ 30 Bí ìjọba Jèhóṣáfátì kò ṣe ní ìyọlẹ́nu mọ́ nìyẹn, Ọlọ́run rẹ̀ sì ń fún un ní ìsinmi níbi gbogbo.+
31 Jèhóṣáfátì ń jọba lórí Júdà nìṣó. Ẹni ọdún márùndínlógójì (35) ni nígbà tó jọba, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ásúbà ọmọ Ṣílíháì.+ 32 Ó ń rìn ní ọ̀nà Ásà bàbá rẹ̀.+ Kò yà kúrò nínú rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà.+ 33 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò,+ àwọn èèyàn náà kò sì tíì múra ọkàn wọn sílẹ̀ fún Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+
34 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóṣáfátì, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Jéhù+ ọmọ Hánáánì,+ èyí tó wà nínú Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì. 35 Lẹ́yìn náà, Jèhóṣáfátì ọba Júdà bá Ahasáyà ọba Ísírẹ́lì da nǹkan pọ̀, ẹni tó ń hùwà burúkú.+ 36 Nítorí náà, ó fi í ṣe alábàáṣiṣẹ́ láti máa ṣe àwọn ọkọ̀ òkun tí á máa lọ sí Táṣíṣì,+ wọ́n sì ṣe àwọn ọkọ̀ òkun náà ní Esioni-gébérì. + 37 Àmọ́, Élíésérì ọmọ Dódáfáhù láti Márẹ́ṣà sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Jèhóṣáfátì, ó ní: “Torí pé o bá Ahasáyà da nǹkan pọ̀, Jèhófà yóò pa iṣẹ́ rẹ run.”+ Nítorí náà, àwọn ọkọ̀ òkun náà fọ́,+ wọn kò sì lè lọ sí Táṣíṣì.
21 Níkẹyìn, Jèhóṣáfátì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì; Jèhórámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+ 2 Àwọn arákùnrin rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Jèhóṣáfátì ni Asaráyà, Jéhíélì, Sekaráyà, Asaráyà, Máíkẹ́lì àti Ṣẹfatáyà; gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Jèhóṣáfátì ọba Ísírẹ́lì. 3 Bàbá wọn fún wọn ní ẹ̀bùn púpọ̀ tó jẹ́ fàdákà àti wúrà pẹ̀lú àwọn nǹkan iyebíye, títí kan àwọn ìlú olódi ní Júdà;+ àmọ́ ó fún Jèhórámù ní ìjọba,+ torí pé òun ni àkọ́bí.
4 Nígbà tí Jèhórámù gorí ìtẹ́ ìjọba bàbá rẹ̀, ó fi idà pa gbogbo àwọn àbúrò rẹ̀+ àti àwọn kan lára àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ipò rẹ̀ fìdí múlẹ̀. 5 Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni Jèhórámù nígbà tó jọba, ọdún mẹ́jọ ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ 6 Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ bí àwọn ọba tó wá láti ilé Áhábù ti ṣe, nítorí ọmọ Áhábù ló fi ṣe aya;+ ó sì ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà. 7 Àmọ́ Jèhófà ò fẹ́ pa ilé Dáfídì run, nítorí májẹ̀mú tó bá Dáfídì dá,+ torí ó ti ṣèlérí pé Dáfídì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lá máa ṣàkóso* títí lọ.+
8 Nígbà ayé rẹ̀, Édómù ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà,+ wọ́n sì fi ọba jẹ lórí ara wọn.+ 9 Nítorí náà, Jèhórámù àti àwọn olórí tó yàn sọdá pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó dìde ní òru, ó sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Édómù tí wọ́n yí i ká àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin. 10 Àmọ́ Édómù ṣì ń ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà títí di òní yìí. Líbínà+ pẹ̀lú ṣọ̀tẹ̀ sí i ní àkókò yẹn, nítorí ó ti fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀ sílẹ̀.+ 11 Òun náà ṣe àwọn ibi gíga + lórí àwọn òkè Júdà, kí ó lè mú àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ó sì kó Júdà ṣìnà.
12 Níkẹyìn, wòlíì Èlíjà kọ ìwé kan sí i,+ ó ní: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ sọ nìyí, ‘Ìwọ kò rìn ní ọ̀nà Jèhóṣáfátì+ bàbá rẹ tàbí ní ọ̀nà Ásà+ ọba Júdà. 13 Àmọ́, ò ń rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ o sì mú kí Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ṣe àgbèrè ẹ̀sìn+ bí àgbèrè tí ilé Áhábù ṣe,+ kódà o pa àwọn arákùnrin rẹ,+ agbo ilé bàbá rẹ, àwọn tó sàn jù ọ́ lọ. 14 Torí náà, Jèhófà yóò mú àjálù ńlá bá àwọn èèyàn rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti gbogbo ohun ìní rẹ. 15 Oríṣiríṣi àìsàn máa ṣe ọ́ pẹ̀lú àrùn tó máa mú ọ ní ìfun, títí àwọn ìfun rẹ á fi tú jáde nítorí àìsàn tí á máa ṣe ọ́ lójoojúmọ́.’”
16 Lẹ́yìn náà, Jèhófà gbé+ àwọn Filísínì*+ àti àwọn ará Arébíà+ tó wà nítòsí àwọn ará Etiópíà dìde sí Jèhórámù. 17 Nítorí náà, wọ́n ya bo Júdà, wọ́n sì fi ipá wọ inú rẹ̀, wọ́n kó gbogbo ohun ìní tó wà nínú ilé* ọba,+ wọ́n tún kó àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀; ọmọ kan ṣoṣo tó ṣẹ́ kù fún un ni Jèhóáhásì,*+ àbíkẹ́yìn rẹ̀. 18 Lẹ́yìn gbogbo èyí, Jèhófà fi àìsàn kan tí kò ṣeé wò sàn kọ lù ú ní ìfun rẹ̀.+ 19 Nígbà tó yá, tí ọdún méjì gbáko ti kọjá, ìfun rẹ̀ tú jáde nítorí àìsàn tó ń ṣe é, ó sì kú nínú ìrora ńlá tí àìsàn náà mú bá a; àwọn èèyàn rẹ̀ kò ṣe ìfinásun nítorí rẹ̀ bí wọ́n ti ṣe ìfinásun nítorí àwọn baba ńlá rẹ̀.+ 20 Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni nígbà tó jọba, ọdún mẹ́jọ ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò sẹ́ni tí ikú rẹ̀ dùn. Torí náà, wọ́n sin ín sí Ìlú Dáfídì,+ àmọ́ kì í ṣe ní ibi tí wọ́n sin àwọn ọba sí.+
22 Nígbà náà, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù fi Ahasáyà ọmọ rẹ̀ àbíkẹ́yìn jọba ní ipò rẹ̀, nítorí àwọn jàǹdùkú* tó tẹ̀ lé àwọn ará Arébíà wá sí ibùdó ti pa gbogbo àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀.+ Torí náà, Ahasáyà ọmọ Jèhórámù bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní Júdà.+ 2 Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ahasáyà nígbà tó jọba, ọdún kan ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ataláyà+ ọmọ ọmọ* Ómírì.+
3 Òun náà ṣe ohun tí àwọn ará ilé Áhábù ṣe,+ nítorí ìyá rẹ̀ ni agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ tó ń gbà á nímọ̀ràn láti máa hùwà burúkú. 4 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà nìṣó, bí ilé Áhábù ti ṣe, nítorí àwọn ni agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú, ìyẹn ló sì fa ìparun rẹ̀. 5 Ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wọn, ó sì bá Jèhórámù ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì lọ láti gbéjà ko Hásáẹ́lì+ ọba Síríà ní Ramoti-gílíádì,+ ibẹ̀ ni àwọn tafàtafà ti ṣe Jèhórámù léṣe. 6 Ó pa dà sí Jésírẹ́lì+ kó lè tọ́jú ọgbẹ́ tí wọ́n dá sí i lára ní Rámà nígbà tó ń bá Hásáẹ́lì ọba Síríà jà.+
Ahasáyà* ọmọ Jèhórámù+ ọba Júdà lọ wo Jèhórámù+ ọmọ Áhábù ní Jésírẹ́lì, torí wọ́n ti ṣe é léṣe.*+ 7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fa ìṣubú Ahasáyà bó ṣe wá sọ́dọ̀ Jèhórámù; nígbà tó dé, ó tẹ̀ lé Jèhórámù lọ sọ́dọ̀ Jéhù+ ọmọ ọmọ* Nímúṣì, ẹni tí Jèhófà ti fòróró yàn láti pa ilé Áhábù run.*+ 8 Nígbà tí Jéhù bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìdájọ́ ṣẹ lórí ilé Áhábù, ó rí àwọn ìjòyè Júdà àti àwọn ọmọ àwọn arákùnrin Ahasáyà pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́ Ahasáyà, ó sì pa wọ́n.+ 9 Lẹ́yìn náà, ó wá Ahasáyà; wọ́n mú un níbi tó sá pa mọ́ sí ní Samáríà, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Jéhù. Wọ́n pa á, wọ́n sì sin ín,+ torí wọ́n sọ pé: “Ọmọ ọmọ Jèhóṣáfátì ni, ẹni tó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ wá Jèhófà.” + Kò sẹ́nì kankan nínú ilé Ahasáyà tó lágbára láti ṣàkóso ilẹ̀ náà.
10 Nígbà tí Ataláyà,+ ìyá Ahasáyà rí i pé ọmọ òun ti kú, ó dìde, ó sì pa gbogbo ìdílé ọba* ilé Júdà run.+ 11 Àmọ́, Jèhóṣábéátì ọmọbìnrin ọba gbé Jèhóáṣì+ ọmọ Ahasáyà, ó jí i gbé láàárín àwọn ọmọ ọba tí wọ́n fẹ́ pa, ó sì fi òun àti obìnrin tó ń tọ́jú rẹ̀ sínú yàrá inú lọ́hùn-ún. Jèhóṣábéátì ọmọbìnrin Ọba Jèhórámù+ (òun ni ìyàwó àlùfáà Jèhóádà,+ òun náà sì ni arábìnrin Ahasáyà) rọ́nà fi í pa mọ́ nítorí Ataláyà, kó má bàa pa á.+ 12 Ọdún mẹ́fà ló fi wà lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́, Ataláyà sì ń ṣàkóso ilẹ̀ náà.
23 Ní ọdún keje, Jèhóádà gbé ìgbésẹ̀ akin, ó sì bá àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ṣe àdéhùn,*+ àwọn ni: Asaráyà ọmọ Jéróhámù, Íṣímáẹ́lì ọmọ Jèhóhánánì, Asaráyà ọmọ Óbédì, Maaseáyà ọmọ Ádáyà àti Élíṣáfátì ọmọ Síkírì. 2 Nígbà náà, wọ́n lọ káàkiri Júdà, wọ́n sì kó àwọn ọmọ Léfì+ jọ látinú gbogbo àwọn ìlú Júdà àti àwọn olórí àwọn agbo ilé ní Ísírẹ́lì. Nígbà tí wọ́n dé sí Jerúsálẹ́mù, 3 gbogbo ìjọ náà bá ọba dá májẹ̀mú+ nínú ilé Ọlọ́run tòótọ́, lẹ́yìn náà, ó sọ fún wọn pé:
“Ẹ wò ó! Ọmọ ọba yóò jọba, bí Jèhófà ti ṣèlérí nípa àwọn ọmọ Dáfídì.+ 4 Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ìdá mẹ́ta lára àwọn àlùfáà àti lára àwọn ọmọ Léfì tó máa wà lẹ́nu iṣẹ́+ ní Sábáàtì máa jẹ́ aṣọ́nà;+ 5 ìdá mẹ́ta míì máa wà ní ilé* ọba,+ ìdá mẹ́ta tó kù á wà ní Ẹnubodè Ìpìlẹ̀, gbogbo àwọn èèyàn náà á sì wà ní àwọn àgbàlá ilé Jèhófà.+ 6 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọ ilé Jèhófà àfi àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tó ń ṣe ìránṣẹ́.+ Àwọn yìí lè wọlé torí pé àwùjọ mímọ́ ni wọ́n, gbogbo àwọn èèyàn náà yóò sì máa ṣe ojúṣe wọn fún Jèhófà. 7 Àwọn ọmọ Léfì gbọ́dọ̀ yí ọba ká, kálukú pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́. Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá wọlé. Kí ẹ sì dúró ti ọba níbikíbi tó bá lọ.”*
8 Àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Júdà ṣe ohun tí àlùfáà Jèhóádà pa láṣẹ fún wọn gẹ́lẹ́. Nítorí náà, kálukú mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní Sábáàtì pẹ̀lú àwọn tí kò sí lẹ́nu iṣẹ́ ní Sábáàtì,+ torí pé àlùfáà Jèhóádà kò tíì ní kí àwọn àwùjọ náà+ kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn. 9 Lẹ́yìn náà, àlùfáà Jèhóádà fún àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ ní àwọn ọ̀kọ̀ àti asà* àti apata* tó jẹ́ ti Ọba Dáfídì,+ tó wà nínú ilé Ọlọ́run tòótọ́.+ 10 Ó wá fi gbogbo àwọn èèyàn náà sí ibi tí wọ́n máa wà, kálukú pẹ̀lú ohun ìjà* rẹ̀ lọ́wọ́, láti apá ọ̀tún ilé náà títí dé apá òsì ilé náà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé náà, gbogbo wọn yí ọba ká. 11 Nígbà náà, wọ́n mú ọmọ ọba+ jáde, wọ́n sì fi adé* dé e, wọ́n fi Ẹ̀rí*+ sí i lórí, wọ́n fi jọba, Jèhóádà àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì fòróró yàn án. Wọ́n sọ pé: “Kí ẹ̀mí ọba ó gùn o!”+
12 Nígbà tí Ataláyà gbọ́ ìró àwọn èèyàn tó ń sáré tí wọ́n sì ń yin ọba, ní kíá, ó lọ bá àwọn tó wà ní ilé Jèhófà.+ 13 Ó wá rí ọba níbẹ̀ tó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó* ní ibi àbáwọlé. Àwọn ìjòyè + àti àwọn tó ń fun kàkàkí wà lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń yọ̀,+ wọ́n sì ń fun kàkàkí, àwọn akọrin tí ohun ìkọrin wà lọ́wọ́ wọn ló sì ń darí* orin ìyìn náà. Ni Ataláyà bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kígbe pé: “Ọ̀tẹ̀ rèé o! Ọ̀tẹ̀ rèé o!” 14 Àmọ́ àlùfáà Jèhóádà kó àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún jáde, àwọn tí a yàn ṣe olórí ọmọ ogun, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ mú un kúrò láàárín àwọn ọmọ ogun, tí ẹnikẹ́ni bá sì tẹ̀ lé e, kí ẹ fi idà pa á!” Nítorí àlùfáà ti sọ pé: “Ẹ má ṣe pa á ní ilé Jèhófà.” 15 Torí náà, wọ́n mú un, nígbà tó sì dé ibi àbáwọlé Ẹnubodè Ẹṣin tó wà ní ilé* ọba, wọ́n pa á níbẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
16 Lẹ́yìn náà, Jèhóádà dá májẹ̀mú láàárín òun àti gbogbo àwọn èèyàn náà àti ọba pé àwọn á máa jẹ́ èèyàn Jèhófà nìṣó.+ 17 Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn èèyàn náà wá sí ilé* Báálì, wọ́n sì wó o lulẹ̀,+ wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ rẹ̀ àti àwọn ère rẹ̀ túútúú,+ wọ́n sì pa Mátánì àlùfáà Báálì+ níwájú àwọn pẹpẹ náà. 18 Jèhóádà wá fi iṣẹ́ àbójútó ilé Jèhófà sí ìkáwọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, àwọn tí Dáfídì yàn sí àwọn àwùjọ tó ń bójú tó ilé Jèhófà láti máa rú àwọn ẹbọ sísun Jèhófà+ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè,+ pẹ̀lú ayọ̀ àti orin, bí Dáfídì ṣe sọ.* 19 Ó tún fi àwọn aṣọ́bodè+ sí àwọn ẹnubodè ilé Jèhófà kí aláìmọ́ èyíkéyìí má bàa wọlé. 20 Ó wá kó àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún,+ àwọn èèyàn pàtàkì, àwọn alákòóso àti gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, ó sì mú ọba wá láti ilé Jèhófà. Wọ́n gba ẹnubodè apá òkè wá sí ilé* ọba, wọ́n sì mú ọba jókòó sórí ìtẹ́+ ìjọba. + 21 Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń yọ̀, ìlú náà sì tòrò, nítorí pé wọ́n ti pa* Ataláyà.
24 Ọmọ ọdún méje ni Jèhóáṣì nígbà tó jọba,+ ogójì (40) ọdún ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sibáyà láti Bíá-ṣébà.+ 2 Jèhóáṣì ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé àlùfáà Jèhóádà.+ 3 Jèhóádà fẹ́ ìyàwó méjì fún un, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.
4 Lẹ́yìn náà, ó wà lọ́kàn Jèhóáṣì láti tún ilé Jèhófà ṣe.+ 5 Torí náà, ó kó àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì jọ, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Júdà kí ẹ sì gba owó lọ́wọ́ gbogbo Ísírẹ́lì láti máa fi tún ilé Ọlọ́run yín+ ṣe lọ́dọọdún; kí ẹ sì tètè gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.” Àmọ́, àwọn ọmọ Léfì kò tètè gbé ìgbésẹ̀.+ 6 Nítorí náà, ọba pe Jèhóádà olórí, ó sì sọ fún un pé:+ “Kí ló dé tí o kò tíì ní kí àwọn ọmọ Léfì mú owó orí mímọ́ tí Mósè+ ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ wá láti Júdà àti Jerúsálẹ́mù, ìyẹn owó orí mímọ́ ti ìjọ Ísírẹ́lì, fún àgọ́ Ẹ̀rí?+ 7 Nítorí àwọn ọmọ Ataláyà,+ obìnrin burúkú yẹn, ti fọ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́ wọlé,+ wọ́n sì ti lo gbogbo àwọn ohun mímọ́ ilé Jèhófà fún àwọn Báálì.” 8 Nígbà náà, àwọn èèyàn kan àpótí + kan bí ọba ṣe pa á láṣẹ, wọ́n sì gbé e sí ìta ẹnubodè ilé Jèhófà.+ 9 Lẹ́yìn náà, wọ́n kéde káàkiri Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé kí wọ́n mú owó orí mímọ́+ tí Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ bù lé Ísírẹ́lì ní aginjù, wá fún Jèhófà. 10 Inú gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn èèyàn náà dùn,+ wọ́n ń mú ọrẹ wá, wọ́n sì ń jù ú sínú àpótí náà títí ó fi kún.*
11 Nígbàkigbà tí àwọn ọmọ Léfì bá gbé àpótí náà wá kí wọ́n lè kó ohun tó wà nínú rẹ̀ fún ọba, tí wọ́n sì rí i pé owó ti pọ̀ nínú rẹ̀, akọ̀wé ọba àti kọmíṣọ́nnà tó ń ṣojú olórí àlùfáà á wá, wọ́n á kó ohun tó wà nínú àpótí+ náà, wọ́n á sì dá a pa dà sí àyè rẹ̀. Ohun tí wọ́n máa ń ṣe nìyẹn lójoojúmọ́, wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ owó kó jọ. 12 Lẹ́yìn náà, ọba àti Jèhóádà á kó o fún àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà, wọ́n á sì háyà àwọn agékùúta àti àwọn oníṣẹ́ ọnà láti tún ilé Jèhófà ṣe,+ títí kan àwọn oníṣẹ́ irin àti bàbà láti tún ilé Jèhófà ṣe. 13 Àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, iṣẹ́ àtúnṣe náà ń tẹ̀ síwájú lábẹ́ àbójútó wọn, wọ́n mú kí ilé Ọlọ́run tòótọ́ pa dà sí bó ṣe yẹ kó wà, wọ́n sì mú kó lágbára. 14 Gbàrà tí wọ́n ṣe tán, wọ́n kó owó tó ṣẹ́ kù wá fún ọba àti Jèhóádà, wọ́n sì fi ṣe àwọn nǹkan èlò fún ilé Jèhófà, àwọn nǹkan èlò fún iṣẹ́ ìsìn àti fún rírú ẹbọ àti àwọn ife àti àwọn nǹkan èlò wúrà àti ti fàdákà.+ Wọ́n máa ń rú àwọn ẹbọ sísun+ déédéé ní ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé Jèhóádà.
15 Nígbà tí Jèhóádà darúgbó, tó sì ti lo ọ̀pọ̀ ọdún, ó kú; ẹni àádóje (130) ọdún ni nígbà tó kú. 16 Nítorí náà, wọ́n sin ín sí Ìlú Dáfídì níbi tí wọ́n ń sin àwọn ọba sí,+ nítorí ó ti ṣe dáadáa ní Ísírẹ́lì+ sí Ọlọ́run tòótọ́ àti sí ilé Rẹ̀.
17 Lẹ́yìn ikú Jèhóádà, àwọn ìjòyè Júdà wọlé wá, wọ́n tẹrí ba fún ọba, ọba sì fetí sí wọn. 18 Wọ́n fi ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sin àwọn òpó òrìṣà* àti àwọn òrìṣà, tó fi di pé Ọlọ́run bínú* sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù nítorí pé wọ́n ti jẹ̀bi. 19 Ó ń rán àwọn wòlíì sáàárín wọn léraléra láti mú wọn pa dà wá sọ́dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì ń kìlọ̀ fún wọn* léraléra, àmọ́ wọn ò gbọ́.+
20 Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé* Sekaráyà ọmọ àlùfáà Jèhóádà,+ ó dúró sórí ibi tó ga láàárín àwọn èèyàn náà, ó sì sọ fún wọn pé: “Ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ sọ nìyí, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tẹ àwọn àṣẹ Jèhófà lójú? Ẹ ò ní ṣàṣeyọrí! Nítorí ẹ ti fi Jèhófà sílẹ̀, òun náà á sì fi yín sílẹ̀.’”+ 21 Àmọ́ wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn,+ wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, ní àgbàlá ilé Jèhófà.+ 22 Bí Ọba Jèhóáṣì kò ṣe rántí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhóádà bàbá rẹ̀* fi hàn sí i nìyẹn, tó sì pa á lọ́mọ. Bí ọmọ náà ṣe ń kú lọ, ó sọ pé: “Kí Jèhófà rí sí i, kí ó sì pè ọ́ wá jíhìn.”+
23 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún,* àwọn ọmọ ogun ará Síríà wá gbéjà ko Jèhóáṣì, wọ́n sì ya wọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+ Lẹ́yìn náà, wọ́n pa gbogbo àwọn ìjòyè+ àwọn èèyàn náà, wọ́n kó gbogbo ẹrù wọn, wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ọba Damásíkù. 24 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun ará Síríà tó ya wá kò pọ̀, Jèhófà fi ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an lé wọn lọ́wọ́,+ nítorí wọ́n ti fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀; torí náà, wọ́n* mú ìdájọ́ ṣẹ sórí Jèhóáṣì. 25 Nígbà tí wọ́n kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ (nítorí wọ́n fi í sílẹ̀ pẹ̀lú ọgbẹ́ yán-na-yàn-na* lára), àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn nítorí ó ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ* àlùfáà Jèhóádà+ sílẹ̀. Wọ́n pa á lórí ibùsùn rẹ̀.+ Bó ṣe kú nìyẹn, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì,+ àmọ́ wọn ò sin ín sí ibi tí wọ́n ń sin àwọn ọba sí.+
26 Àwọn tó dìtẹ̀+ mọ́ ọn nìyí: Sábádì ọmọ Ṣíméátì ọmọbìnrin Ámónì àti Jèhósábádì ọmọ Ṣímúrítì ọmọbìnrin Móábù. 27 Ní ti àwọn ọmọ rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ìkéde tí wọ́n ké lé e lórí+ àti àtúnṣe* ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ gbogbo nǹkan yìí wà ní àkọsílẹ̀* nínú Ìwé Àwọn Ọba. Amasááyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
25 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Amasááyà nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jèhóádánì láti Jerúsálẹ́mù.+ 2 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀. 3 Nígbà tí ìjọba rẹ̀ ti fìdí múlẹ̀ dáadáa, ó pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n pa bàbá rẹ̀ ọba.+ 4 Àmọ́ kò pa àwọn ọmọ wọn, torí pé ó ṣe ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin, nínú ìwé Mósè, níbi tí Jèhófà ti pàṣẹ pé: “Àwọn bàbá kò gbọ́dọ̀ kú nítorí àwọn ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ kò gbọ́dọ̀ kú nítorí àwọn bàbá; kí kálukú kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀.”+
5 Amasááyà wá kó gbogbo Júdà jọ, ó sì ní kí wọ́n dúró ní agboolé-agboolé, sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ní gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì.+ Ó forúkọ wọn sílẹ̀ láti ẹni ogún (20) ọdún sókè,+ ó rí i pé wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) akọgun* tó ń ṣiṣẹ́ ológun, tí wọ́n sì lè lo aṣóró àti apata ńlá. 6 Bákan náà, ó fi ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì* fàdákà háyà ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) jagunjagun tó lákíkanjú láti Ísírẹ́lì. 7 Àmọ́, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ kan wá bá a, ó sì sọ pé: “Ọba, má ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì bá ọ lọ, torí Jèhófà kò sí lẹ́yìn Ísírẹ́lì,+ kò sí lẹ́yìn ìkankan lára àwọn ọmọ Éfúrémù. 8 Ìwọ fúnra rẹ ni kí o lọ, kí o gbé ìgbésẹ̀, kí o sì ṣe bí akin lójú ogun. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run tòótọ́ lè mú kí o kọsẹ̀ níwájú ọ̀tá, nítorí Ọlọ́run ní agbára láti ranni lọ́wọ́+ àti láti múni kọsẹ̀.” 9 Ni Amasááyà bá sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà pé: “Ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì tí mo wá fún àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ńkọ́?” Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà fèsì pé: “Jèhófà mọ bó ṣe máa fi èyí tó pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ san án fún ọ.”+ 10 Torí náà, Amasááyà ní kí àwọn ọmọ ogun tó wá láti Éfúrémù máa lọ, pé kí wọ́n pa dà sí àyè wọn. Àmọ́, inú bí wọn gidigidi sí Júdà, wọ́n sì pa dà sí àyè wọn tìbínútìbínú.
11 Lẹ́yìn náà, Amasááyà mọ́kàn le, ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí Àfonífojì Iyọ̀,+ ó sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lára àwọn ọkùnrin Séírì.+ 12 Àwọn ọkùnrin Júdà wá mú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) láàyè. Wọ́n kó wọn wá sí orí àpáta, wọ́n sì jù wọ́n láti orí àpáta náà, gbogbo wọn sì já jálajàla. 13 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun tí Amasááyà dá pa dà pé kí wọ́n má ṣe bá òun lọ sí ogun+ wá ń kó ẹrù àwọn tó ń gbé ní àwọn ìlú Júdà, láti Samáríà+ títí dé Bẹti-hórónì,+ wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ẹrù.
14 Ṣùgbọ́n, nígbà tí Amasááyà dé láti ibi tó ti lọ pa àwọn ọmọ Édómù, ó mú àwọn ọlọ́run àwọn ọmọ Séírì wá, ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́run fún ara rẹ̀,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í forí balẹ̀ níwájú wọn, ó sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí wọn. 15 Nítorí náà, Jèhófà bínú gan-an sí Amasááyà, ó sì rán wòlíì kan sí i tó sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi ń sin àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tí kò gba àwọn èèyàn wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ?”+ 16 Bó ṣe ń bá a sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ọba sọ pé: “Ṣé a fi ọ́ ṣe agbani-nímọ̀ràn ọba ni?+ Dákẹ́!+ Àbí o fẹ́ kí wọ́n pa ọ́ ni?” Àmọ́, kí wòlíì náà tó dákẹ́, ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé Ọlọ́run ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò sì fetí sí ìmọ̀ràn mi.”+
17 Lẹ́yìn tí Amasááyà ọba Júdà fọ̀rọ̀ lọ àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀, ó ránṣẹ́ sí Jèhóáṣì ọmọ Jèhóáhásì ọmọ Jéhù ọba Ísírẹ́lì pé: “Wá, jẹ́ ká dojú ìjà kọ ara wa.”*+ 18 Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì ránṣẹ́ sí Amasááyà ọba Júdà pé: “Èpò ẹlẹ́gùn-ún tó wà ní Lẹ́bánónì ránṣẹ́ sí igi kédárì tó wà ní Lẹ́bánónì, pé, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi kó fi ṣe aya.’ Àmọ́, ẹranko kan láti Lẹ́bánónì kọjá, ó sì tẹ èpò ẹlẹ́gùn-ún náà pa. 19 Ò ń sọ pé, ‘Wò ó! Mo* ti ṣẹ́gun Édómù.’+ Torí bẹ́ẹ̀, ìgbéraga wọ̀ ẹ́ lẹ́wù, o sì fẹ́ kí àwọn èèyàn máa gbé ògo fún ọ. Àmọ́ ní báyìí, dúró sí ilé* rẹ. Kí ló dé tí wàá fi fa àjálù bá ara rẹ, tí wàá sì gbé ara rẹ àti Júdà ṣubú?”
20 Ṣùgbọ́n Amasááyà ò gbọ́,+ torí pé látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ ni èyí ti wá kí ó lè fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́,+ nítorí pé wọ́n sin àwọn ọlọ́run Édómù.+ 21 Torí náà, Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì jáde lọ, òun àti Amasááyà ọba Júdà sì dojú ìjà kọra ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì, + tó jẹ́ ti Júdà. 22 Ísírẹ́lì ṣẹ́gun Júdà, kálukú sì sá lọ sí ilé* rẹ̀. 23 Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì mú Amasááyà ọba Júdà, ọmọ Jèhóáṣì ọmọ Jèhóáhásì,* ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì. Lẹ́yìn náà, ó mú un wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣe àlàfo sára ògiri Jerúsálẹ́mù láti Ẹnubodè Éfúrémù+ títí dé Ẹnubodè Igun,+ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ìgbọ̀nwọ́.* 24 Ó kó gbogbo wúrà àti fàdákà pẹ̀lú gbogbo ohun èlò tó wà ní ilé Ọlọ́run tòótọ́ lọ́dọ̀* Obedi-édómù àti ní àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba+ àti àwọn tí wọ́n mú lóǹdè. Lẹ́yìn náà, ó pa dà sí Samáríà.
25 Amasááyà+ ọmọ Jèhóáṣì ọba Júdà lo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sí i lẹ́yìn ikú Jèhóáṣì+ ọmọ Jèhóáhásì ọba Ísírẹ́lì.+ 26 Ní ti ìyókù ìtàn Amasááyà, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wò ó! ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì? 27 Láti ìgbà tí Amasááyà ti pa dà lẹ́yìn Jèhófà ni wọ́n ti ń dìtẹ̀+ mọ́ ọn ní Jerúsálẹ́mù, ó sì sá lọ sí Lákíṣì, àmọ́ wọ́n rán àwọn kan tẹ̀ lé e lọ sí Lákíṣì, wọ́n sì pa á síbẹ̀. 28 Nítorí náà, wọ́n fi ẹṣin gbé e pa dà, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí ìlú Júdà.
26 Nígbà náà, gbogbo àwọn èèyàn Júdà mú Ùsáyà+ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), wọ́n sì fi í jọba ní ipò Amasááyà+ bàbá rẹ̀. 2 Ó tún Élótì + kọ́, ó sì dá a pa dà fún Júdà lẹ́yìn tí ọba* ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀.+ 3 Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ni Ùsáyà+ nígbà tó jọba, ọdún méjìléláàádọ́ta (52) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jekoláyà tó wá láti Jerúsálẹ́mù.+ 4 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà nìṣó bí Amasááyà bàbá rẹ̀ ti ṣe.+ 5 Ó ń wá Ọlọ́run ní ìgbà ayé Sekaráyà, ẹni tó kọ́ ọ láti máa bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́. Ní gbogbo àkókò tó ń wá Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ mú kí ó láásìkí.+
6 Ó jáde lọ bá àwọn Filísínì jà,+ ó sì fọ́ ògiri Gátì+ àti ògiri Jábínè+ àti ògiri Áṣídódì+ wọlé. Lẹ́yìn náà, ó kọ́ àwọn ìlú sí ìpínlẹ̀ Áṣídódì àti sáàárín àwọn Filísínì. 7 Ọlọ́run tòótọ́ ń ràn án lọ́wọ́ láti bá àwọn Filísínì jà àti àwọn ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ tó ń gbé ní Gọbáálì àti àwọn Méúnímù. 8 Àwọn ọmọ Ámónì+ bẹ̀rẹ̀ sí í fún Ùsáyà ní ìṣákọ́lẹ̀.* Nígbà tó yá, òkìkí rẹ̀ kàn dé Íjíbítì, nítorí ó ti di alágbára ńlá. 9 Yàtọ̀ síyẹn, Ùsáyà kọ́ àwọn ilé gogoro+ sí Jerúsálẹ́mù lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ẹnubodè Igun+ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ẹnubodè Àfonífojì+ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ìtì Ògiri, ó sì mú kí wọ́n lágbára. 10 Ó tún kọ́ àwọn ilé gogoro+ sí aginjù, ó sì gbẹ́ kòtò omi púpọ̀* (nítorí ó ní ẹran ọ̀sìn tó pọ̀ gan-an); ó ṣe bákan náà ní Ṣẹ́fẹ́là àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀.* Ó ní àwọn àgbẹ̀ àti àwọn tó ń rẹ́wọ́ àjàrà ní àwọn òkè àti ní Kámẹ́lì, nítorí ó fẹ́ràn iṣẹ́ àgbẹ̀.
11 Bákan náà, Ùsáyà ní àwọn ọmọ ogun tó ti gbára dì fún ogun. Wọ́n máa ń jáde ogun, wọ́n á sì to ara wọn ní àwùjọ-àwùjọ. Jéélì akọ̀wé+ àti Maaseáyà tó jẹ́ aláṣẹ ló kà wọ́n, wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀+ lábẹ́ àṣẹ Hananáyà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba. 12 Iye gbogbo àwọn olórí agbo ilé tí wọ́n ń bójú tó àwọn akíkanjú jagunjagun yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (2,600). 13 Ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹgbẹ̀rún méje àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (307,500) àwọn ológun ló wà lábẹ́ àṣẹ wọn, wọ́n sì ti múra ogun, wọ́n jẹ́ àwùjọ ọmọ ogun tó máa ti ọba lẹ́yìn láti gbógun ti ọ̀tá.+ 14 Ùsáyà fún gbogbo àwọn ọmọ ogun náà ní apata, aṣóró,+ akoto,* ẹ̀wù irin,+ ọfà* àti òkúta kànnàkànnà.+ 15 Láfikún sí i, ó ṣe àwọn ẹ̀rọ ogun ní Jerúsálẹ́mù, èyí tí àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ṣe; orí àwọn ilé gogoro+ àti àwọn igun odi ni wọ́n kó wọn lé, wọ́n sì lè ta ọfà àti òkúta ńlá. Torí náà, òkìkí rẹ̀ kàn délé dóko, torí ó rí ìrànlọ́wọ́ púpọ̀ gbà, ó sì di alágbára.
16 Àmọ́, bó ṣe di alágbára tán, ìgbéraga wọ̀ ọ́ lẹ́wù débi tó fi fa àjálù bá ara rẹ̀, ó hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bó ṣe wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.+ 17 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àlùfáà Asaráyà àti ọgọ́rin (80) àlùfáà Jèhófà tó nígboyà wọlé tẹ̀ lé e. 18 Wọ́n kojú Ọba Ùsáyà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ùsáyà, kò tọ́ sí ọ láti sun tùràrí sí Jèhófà!+ Àwọn àlùfáà nìkan ló yẹ kó máa sun tùràrí, torí àwọn ni àtọmọdọ́mọ Áárónì,+ àwọn tí a ti yà sí mímọ́. Jáde kúrò ní ibi mímọ́, nítorí o ti hùwà àìṣòótọ́, o ò sì ní rí ògo kankan gbà lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run nítorí èyí.”
19 Àmọ́ inú bí Ùsáyà nígbà tí àwo tó fẹ́ fi sun tùràrí ti wà lọ́wọ́ rẹ̀;+ bí inú ṣe ń bí i sí àwọn àlùfáà lọ́wọ́, ẹ̀tẹ̀+ yọ níwájú orí rẹ̀ níṣojú àwọn àlùfáà nínú ilé Jèhófà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ tùràrí. 20 Nígbà tí Asaráyà olórí àlùfáà àti gbogbo àlùfáà yíjú sí i, wọ́n rí i pé ẹ̀tẹ̀ ti kọ lù ú níwájú orí! Nítorí náà, wọ́n sáré mú un jáde kúrò níbẹ̀, òun náà sì tètè jáde, nítorí Jèhófà ti kọ lù ú.
21 Ọba Ùsáyà ya adẹ́tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, ilé tó wà lọ́tọ̀ ló sì ń gbé torí pé adẹ́tẹ̀ ni,+ wọn ò sì jẹ́ kó wá sí ilé Jèhófà mọ́. Jótámù ọmọ rẹ̀ ló wá ń bójú tó ilé* ọba, ó sì ń dá ẹjọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà.+
22 Ìyókù ìtàn Ùsáyà, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni wòlíì Àìsáyà+ ọmọ Émọ́ọ̀sì kọ sílẹ̀. 23 Níkẹyìn, Ùsáyà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, àmọ́ pápá ìsìnkú tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí wọ́n ń sin àwọn ọba sí ni wọ́n sin ín sí, torí wọ́n sọ pé: “Adẹ́tẹ̀ ni.” Jótámù+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
27 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Jótámù+ nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jérúṣà ọmọ Sádókù.+ 2 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Ùsáyà bàbá rẹ̀ ti ṣe,+ àmọ́ ní tirẹ̀, kò wọ ibi tí kò yẹ kó wọ̀ nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà.+ Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà ṣì ń hùwà ibi. 3 Ó kọ́ ẹnubodè apá òkè ilé Jèhófà,+ ó kọ́ ohun púpọ̀ sórí ògiri Ófélì.+ 4 Ó tún kọ́ àwọn ìlú+ sí agbègbè olókè Júdà,+ ó sì kọ́ àwọn ibi olódi+ àti àwọn ilé gogoro+ sí agbègbè onígi. 5 Ó bá ọba àwọn ọmọ Ámónì jà,+ ó sì borí wọn níkẹyìn, tí ó fi jẹ́ pé ní ọdún yẹn, àwọn ọmọ Ámónì fún un ní ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì* fàdákà àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* àlìkámà* àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ti ọkà bálì. Àwọn ọmọ Ámónì tún san èyí fun un ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta.+ 6 Báyìí ni Jótámù ń lágbára sí i, nítorí ó pinnu* láti máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.
7 Ní ti ìyókù ìtàn Jótámù, gbogbo àwọn ogun tó jà àti àwọn ọ̀nà rẹ̀, ó wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà.+ 8 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ 9 Níkẹyìn, Jótámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì.+ Áhásì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+
28 Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì+ nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ 2 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ kódà ó fi irin ṣe ère*+ àwọn Báálì. 3 Yàtọ̀ síyẹn, ó mú ẹbọ rú èéfín ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,* ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná,+ ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe. 4 Ó tún ń rúbọ, ó sì ń mú ẹbọ rú èéfín lórí àwọn ibi gíga,+ lórí àwọn òkè àti lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+
5 Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ fi í lé ọwọ́ ọba Síríà,+ tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀, tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́rú, wọ́n kó wọn wá sí Damásíkù.+ Ọlọ́run tún fi í lé ọwọ́ ọba Ísírẹ́lì, ẹni tó pa òun àti àwọn èèyàn rẹ̀ lọ rẹpẹtẹ. 6 Pékà+ ọmọ Remaláyà pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ní Júdà ní ọjọ́ kan, gbogbo wọn jẹ́ akíkanjú ọkùnrin, èyí sì ṣẹlẹ̀ nítorí pé wọ́n ti fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀.+ 7 Síkírì, jagunjagun kan látinú ẹ̀yà Éfúrémù, pa Maaseáyà ọmọ ọba àti Ásíríkámù, ẹni tó ń bójú tó ààfin* àti Ẹlikénà igbá kejì ọba. 8 Bákan náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) lára àwọn arákùnrin wọn lẹ́rú, àwọn obìnrin, àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin; wọ́n tún gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù, wọ́n sì kó àwọn ẹrù náà wá sí Samáríà.+
9 Àmọ́ wòlíì Jèhófà kan wà níbẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ódédì. Ó lọ pàdé àwọn ọmọ ogun tó ń bọ̀ ní Samáríà, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín bínú sí Júdà ló ṣe fi wọ́n lé yín lọ́wọ́,+ ẹ sì fi ìbínú tó ga dé ọ̀run pa wọ́n. 10 Ní báyìí, ẹ fẹ́ fi àwọn èèyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe ìránṣẹ́ yín.+ Àmọ́, ṣé ẹ̀yin náà ò jẹ̀bi níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín ni? 11 Ẹ fetí sí mi kí ẹ sì dá àwọn tí ẹ mú lẹ́rú látinú àwọn arákùnrin yín pa dà, nítorí ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná wà lórí yín.”
12 Ìgbà náà ni àwọn kan lára ìjòyè àwọn ọmọ Éfúrémù, Asaráyà ọmọ Jèhóhánánì, Berekáyà ọmọ Méṣílémótì àti Jehisikáyà ọmọ Ṣálúmù àti Ámásà ọmọ Hádíláì, wá kojú àwọn tó ń bọ̀ láti ojú ogun, 13 wọ́n sì sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe kó àwọn tí ẹ mú lẹ́rú wá sí ibí yìí, torí ó máa mú ká jẹ̀bi lójú Jèhófà. Ohun tí ẹ fẹ́ ṣe yìí máa dá kún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti ẹ̀bi wa, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa ti pọ̀ gan-an, ìbínú tó ń jó bí iná sì wà lórí Ísírẹ́lì.” 14 Torí náà, àwọn ọmọ ogun tó dira ogun náà fa àwọn tí wọ́n mú lẹ́rú àti àwọn ẹrù tí wọ́n kó+ lé ọwọ́ àwọn ìjòyè náà àti gbogbo ìjọ náà. 15 Nígbà náà, àwọn ọkùnrin tí wọ́n yàn dìde, wọ́n kó àwọn tí wọ́n mú lẹ́rú, wọ́n sì fún gbogbo àwọn tó wà ní ìhòòhò lára wọn ní aṣọ látinú àwọn ẹrù tí wọ́n kó. Wọ́n fún wọn ní aṣọ, bàtà, oúnjẹ àti ohun mímu pẹ̀lú òróró tí wọ́n á fi para. Bákan náà, wọ́n fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gbé àwọn tí kò lókun nínú, wọ́n sì gbé wọn wá sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Jẹ́ríkò, ìlú ọlọ́pẹ. Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí Samáríà.
16 Ní àkókò náà, Ọba Áhásì ní kí àwọn ọba Ásíríà ran òun lọ́wọ́.+ 17 Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ọmọ Édómù ya wọlé, wọ́n gbéjà ko Júdà, wọ́n sì kó àwọn èèyàn lẹ́rú. 18 Àwọn Filísínì+ náà tún wá kó ẹrù àwọn èèyàn ní àwọn ìlú Ṣẹ́fẹ́là+ àti Négébù ti Júdà, wọ́n sì gba Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ Áíjálónì,+ Gédérótì, Sókò àti àwọn àrọko rẹ̀,* Tímúnà+ àti àwọn àrọko rẹ̀ pẹ̀lú Gímúsò àti àwọn àrọko rẹ̀; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé níbẹ̀. 19 Jèhófà rẹ Júdà wálẹ̀ nítorí Áhásì ọba Ísírẹ́lì, torí ó ti jẹ́ kí ìwàkiwà gbilẹ̀ ní Júdà, èyí sì mú kí wọ́n máa hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà lọ́nà tó ga.
20 Níkẹyìn, Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà wá gbéjà kò ó, ó sì kó ìdààmú bá a+ dípò kó fún un lókun. 21 Áhásì ti kó àwọn nǹkan tó wà ní ilé Jèhófà àti ilé* ọba+ àti ilé àwọn ìjòyè, ó sì fi ṣe ẹ̀bùn fún ọba Ásíríà; àmọ́ kò ṣe é láǹfààní kankan. 22 Nígbà tí Ọba Áhásì wà nínú ìdààmú, ńṣe ló túbọ̀ ń hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà. 23 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í rúbọ sí àwọn ọlọ́run àwọn ará Damásíkù + tí wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀,+ ó ń sọ pé: “Nítorí pé àwọn ọlọ́run àwọn ọba Síríà ń ràn wọ́n lọ́wọ́, èmi náà á rúbọ sí wọn kí wọ́n lè ràn mí lọ́wọ́.”+ Àmọ́ ńṣe ni wọ́n ṣàkóbá fún òun àti gbogbo Ísírẹ́lì. 24 Yàtọ̀ síyẹn, Áhásì kó àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́ jọ; ó sì gé àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́ sí wẹ́wẹ́,+ ó ti àwọn ilẹ̀kùn ilé Jèhófà pa,+ ó sì ṣe àwọn pẹpẹ fún ara rẹ̀ sí gbogbo igun ọ̀nà Jerúsálẹ́mù. 25 Ní gbogbo àwọn ìlú Júdà, ó ṣe àwọn ibi gíga tí wọ́n ti ń mú ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run míì,+ ó sì mú Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀ bínú.
26 Ní ti ìyókù ìtàn rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì.+ 27 Níkẹyìn, Áhásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí ìlú náà, ní Jerúsálẹ́mù, nítorí wọn kò gbé e wá sí ibi tí wọ́n sin àwọn ọba Ísírẹ́lì sí.+ Hẹsikáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
29 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Hẹsikáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ábíjà ọmọ Sekaráyà.+ 2 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ 3 Ní ọdún kìíní ìjọba rẹ̀, ní oṣù kìíní, ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ilé Jèhófà, ó sì tún wọn ṣe.+ 4 Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wọlé, ó sì kó wọn jọ sí ibi gbayawu ní apá ìlà oòrùn. 5 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ọmọ Léfì. Ní báyìí, ẹ ya ara yín sí mímọ́,+ kí ẹ ya ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín sí mímọ́, kí ẹ sì mú ohun àìmọ́ kúrò nínú ibi mímọ́.+ 6 Nítorí àwọn bàbá wa ti hùwà àìṣòótọ́, wọ́n sì ti ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run wa.+ Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n yí ojú wọn kúrò níbi àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, wọ́n sì kẹ̀yìn sí i.+ 7 Bákan náà, wọ́n ti àwọn ilẹ̀kùn ibi àbáwọlé,*+ wọ́n sì pa àwọn fìtílà.+ Wọn kò sun tùràrí mọ́,+ wọn kò sì rú ẹbọ sísun+ ní ibi mímọ́ sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 8 Jèhófà bínú sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù,+ ó sì sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù, ohun ìyàlẹ́nu àti ẹni àrísúfèé,* bí ẹ̀yin náà ṣe fojú ara yín rí i.+ 9 Idà ti pa àwọn baba ńlá wa,+ àwọn ọmọkùnrin wa, àwọn ọmọbìnrin wa àti àwọn ìyàwó wa sì ti lọ sóko ẹrú nítorí nǹkan yìí.+ 10 Ní báyìí, ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi láti bá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú,+ kí ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná lè kúrò lórí wa. 11 Ẹ̀yin ọmọ mi, kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ ká dẹra nù,* nítorí Jèhófà ti yàn yín láti máa dúró níwájú rẹ̀, kí ẹ lè máa ṣe ìránṣẹ́ fún un,+ kí ẹ sì lè máa mú àwọn ẹbọ rẹ̀ rú èéfín.”+
12 Ni àwọn ọmọ Léfì bá dìde, àwọn ni: Máhátì ọmọ Ámásáì àti Jóẹ́lì ọmọ Asaráyà tó wá látinú àwọn ọmọ Kóhátì;+ látinú àwọn ọmọ Mérárì,+ Kíṣì ọmọ Ábídì àti Asaráyà ọmọ Jéhálélélì; látinú àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì,+ Jóà ọmọ Símà àti Édẹ́nì ọmọ Jóà; 13 látinú àwọn ọmọ Élísáfánì, Ṣímúrì àti Júẹ́lì; látinú àwọn ọmọ Ásáfù,+ Sekaráyà àti Matanáyà; 14 látinú àwọn ọmọ Hémánì,+ Jéhíélì àti Ṣíméì; látinú àwọn ọmọ Jédútúnì,+ Ṣemáyà àti Úsíélì. 15 Nígbà náà, wọ́n kó àwọn arákùnrin wọn jọ, wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ọba pa láṣẹ, láti fọ ilé Jèhófà mọ́.+ 16 Lẹ́yìn náà, àwọn àlùfáà wọ inú ilé Jèhófà láti ṣe ìwẹ̀mọ́, wọ́n sì kó gbogbo ohun àìmọ́ tí wọ́n rí nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà jáde sí àgbàlá+ ilé Jèhófà. Àwọn ọmọ Léfì wá kó wọn, wọ́n sì gbé wọn jáde lọ sí Àfonífojì Kídírónì.+ 17 Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìyàsímímọ́ ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní nìyẹn, ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà, wọ́n dé ibi tí wọ́n ń gbà wọ* ilé Jèhófà.+ Wọ́n fi ọjọ́ mẹ́jọ ya ilé Jèhófà sí mímọ́, wọ́n sì parí rẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kìíní.
18 Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Ọba Hẹsikáyà, wọ́n sọ pé: “A ti fọ gbogbo ilé Jèhófà mọ́, pẹpẹ ẹbọ sísun+ pẹ̀lú gbogbo nǹkan èlò rẹ̀+ àti tábìlì búrẹ́dì onípele*+ pẹ̀lú gbogbo nǹkan èlò rẹ̀. 19 A ti ṣètò gbogbo nǹkan èlò tí Ọba Áhásì pa tì lákòókò ìjọba rẹ̀ nígbà tó hùwà àìṣòótọ́,+ a ti yà wọ́n sí mímọ́,+ wọ́n sì wà níwájú pẹpẹ Jèhófà.”
20 Ọba Hẹsikáyà dìde ní àárọ̀ kùtù, ó kó àwọn ìjòyè ìlú jọ, wọ́n sì lọ sí ilé Jèhófà. 21 Wọ́n mú akọ màlúù méje wá àti àgbò méje àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba náà àti fún ibi mímọ́ àti fún Júdà.+ Nítorí náà, ó sọ fún àwọn àlùfáà, ìyẹn àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì pé kí wọ́n fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Jèhófà. 22 Nígbà náà, wọ́n pa àwọn màlúù náà,+ àwọn àlùfáà gba ẹ̀jẹ̀ wọn, wọ́n sì wọ́n ọn sórí pẹpẹ;+ lẹ́yìn náà, wọ́n pa àwọn àgbò náà, wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ, wọ́n pa àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn náà, wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ. 23 Lẹ́yìn náà, wọ́n mú àwọn akọ ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá síwájú ọba àti ìjọ náà, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn. 24 Àwọn àlùfáà pa wọ́n, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lórí pẹpẹ, láti ṣe ètùtù fún gbogbo Ísírẹ́lì, nítorí ọba ti sọ pé gbogbo Ísírẹ́lì ni kí ẹbọ sísun náà àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà wà fún.
25 Ní àkókò yìí, ó ní kí àwọn ọmọ Léfì dúró sí ilé Jèhófà, pẹ̀lú síńbálì* àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù,+ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dáfídì + àti ti Gádì+ aríran ọba àti ti wòlíì Nátánì,+ nítorí pé Jèhófà ló pa àṣẹ náà nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀. 26 Nítorí náà, àwọn ọmọ Léfì dúró pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin Dáfídì lọ́wọ́, àwọn àlùfáà sì dúró pẹ̀lú kàkàkí lọ́wọ́.+
27 Nígbà náà, Hẹsikáyà pàṣẹ pé kí wọ́n rú ẹbọ sísun náà lórí pẹpẹ.+ Nígbà tí ẹbọ sísun náà bẹ̀rẹ̀, orin Jèhófà bẹ̀rẹ̀, kàkàkí sì bẹ̀rẹ̀ sí í dún, wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ohun ìkọrin Dáfídì ọba Ísírẹ́lì. 28 Gbogbo ìjọ náà forí balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń kọrin, tí kàkàkí sì ń dún, gbogbo èyí ń bá a lọ títí ẹbọ sísun náà fi parí. 29 Gbàrà tí wọ́n parí ẹbọ rírú, ọba àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wólẹ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀. 30 Ọba Hẹsikáyà àti àwọn ìjòyè wá sọ fún àwọn ọmọ Léfì pé kí wọ́n fi àwọn ọ̀rọ̀ Dáfídì+ àti ti Ásáfù+ aríran yin Jèhófà. Nítorí náà, wọ́n kọrin ìyìn tayọ̀tayọ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀.
31 Lẹ́yìn náà, Hẹsikáyà sọ pé: “Ní báyìí tí a ti yà yín sọ́tọ̀* fún Jèhófà, ẹ mú àwọn ẹbọ àti àwọn ẹbọ ìdúpẹ́ wá sí ilé Jèhófà.” Ni ìjọ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ẹbọ àti àwọn ẹbọ ìdúpẹ́ wá, gbogbo ẹni tí ọkàn rẹ̀ múra tán sì mú àwọn ẹbọ sísun wá.+ 32 Iye ẹran ẹbọ sísun tí ìjọ náà mú wá jẹ́ àádọ́rin (70) màlúù, ọgọ́rùn-ún (100) àgbò, igba (200) akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, gbogbo èyí ni wọ́n fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà,+ 33 ọrẹ mímọ́ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) màlúù àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn. 34 Àmọ́ kò sí àwọn àlùfáà tó pọ̀ tó láti bó awọ gbogbo ẹran ẹbọ sísun náà, torí náà, àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì ràn wọ́n lọ́wọ́+ títí iṣẹ́ náà fi parí àti títí àwọn àlùfáà fi parí yíya ara wọn sí mímọ́,+ nítorí ó jẹ àwọn ọmọ Léfì lọ́kàn* láti ya ara wọn sí mímọ́ ju bó ṣe jẹ àwọn àlùfáà lọ́kàn lọ. 35 Bákan náà, ọ̀pọ̀ ẹbọ sísun ló wà,+ títí kan àwọn ibi tó lọ́ràá lára àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ àti àwọn ọrẹ ohun mímu fún àwọn ẹbọ sísun.+ Bí wọ́n ṣe mú iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà pa dà bọ̀ sípò* nìyẹn. 36 Nítorí náà, Hẹsikáyà àti gbogbo àwọn èèyàn náà yọ̀ lórí ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ ṣe fún àwọn èèyàn náà,+ torí pé láìròtẹ́lẹ̀ ni gbogbo nǹkan yìí ṣẹlẹ̀.
30 Hẹsikáyà ránṣẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì+ àti Júdà, ó tiẹ̀ tún kọ lẹ́tà sí Éfúrémù àti Mánásè,+ pé kí wọ́n wá sí ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù láti wá ṣe Ìrékọjá sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 2 Àmọ́, ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn* ní Jerúsálẹ́mù pinnu láti ṣe Ìrékọjá náà ní oṣù kejì,+ 3 nítorí wọn ò lè ṣe é ní àkókò tó yẹ kí wọ́n ṣe é,+ torí pé àwọn àlùfáà tó ti ya ara wọn sí mímọ́ kò pọ̀ tó + àti pé àwọn èèyàn náà kò tíì kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù. 4 Ètò yìí dára lójú ọba àti lójú gbogbo àwọn èèyàn* náà. 5 Nítorí náà, wọ́n pinnu láti kéde káàkiri gbogbo Ísírẹ́lì, láti Bíá-ṣébà dé Dánì,+ pé kí àwọn èèyàn wá ṣe Ìrékọjá sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù, torí wọn ò tíì máa ṣe é pa pọ̀ bó ṣe wà lákọsílẹ̀.+
6 Lẹ́yìn náà, àwọn asáréjíṣẹ́* lọ káàkiri gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà pẹ̀lú àwọn lẹ́tà látọ̀dọ̀ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á láṣẹ, ó ní: “Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, kí ó lè pa dà sọ́dọ̀ àwọn tó ṣẹ́ kù tí wọ́n sá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Ásíríà.+ 7 Ẹ má dà bí àwọn baba ńlá yín àti àwọn arákùnrin yín tó hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, tí ó fi sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù, bí ẹ̀yin náà ṣe rí i.+ 8 Ní báyìí, ẹ má ṣorí kunkun bí àwọn baba ńlá yín.+ Ẹ fi ara yín fún Jèhófà, kí ẹ wá sí ibi mímọ́ rẹ̀+ tó ti yà sí mímọ́ títí láé, kí ẹ sì máa sin Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ìbínú rẹ̀ tó ń jó fòfò lè kúrò lórí yín.+ 9 Torí ìgbà tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà ni àwọn arákùnrin yín àti àwọn ọmọ yín máa rí àánú gbà látọ̀dọ̀ àwọn tó mú wọn lẹ́rú,+ wọ́n á sì jẹ́ kí wọ́n pa dà sí ilẹ̀ yìí,+ nítorí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò* àti aláàánú,+ kò sì ní yí ojú rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ yín tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀.”+
10 Torí náà, àwọn asáréjíṣẹ́* lọ láti ìlú dé ìlú káàkiri ilẹ̀ Éfúrémù àti Mánásè,+ kódà wọ́n dé Sébúlúnì, àmọ́ àwọn èèyàn ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.+ 11 Ṣùgbọ́n, àwọn kan láti Áṣérì, Mánásè àti Sébúlúnì rẹ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 12 Bákan náà, ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́ wà ní Júdà láti mú wọn ṣọ̀kan* kí wọ́n lè ṣe ohun tí ọba àti àwọn ìjòyè pa láṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà.
13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù láti ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú+ ní oṣù kejì;+ àwọn èèyàn náà jẹ́ ìjọ ńlá. 14 Wọ́n dìde, wọ́n sì mú àwọn pẹpẹ tó wà ní Jerúsálẹ́mù kúrò,+ wọ́n kó gbogbo àwọn pẹpẹ tùràrí kúrò,+ wọ́n sì kó wọn dà sí Àfonífojì Kídírónì. 15 Lẹ́yìn náà, wọ́n pa ẹran ẹbọ Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì. Ìtìjú bá àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, torí náà, wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì mú àwọn ẹbọ sísun wá sí ilé Jèhófà. 16 Wọ́n dúró sí àyè wọn, bí Òfin Mósè èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe sọ; lẹ́yìn náà, àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀+ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Léfì. 17 Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà ní ìjọ náà ni kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, àwọn ọmọ Léfì ló sì ń bójú tó pípa àwọn ẹran ẹbọ Ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí kò mọ́,+ láti yà wọ́n sí mímọ́ fún Jèhófà. 18 Nítorí ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà, pàápàá àwọn tó wá láti Éfúrémù, Mánásè,+ Ísákà àti Sébúlúnì ni kò tíì wẹ ara wọn mọ́, síbẹ̀ wọ́n jẹ Ìrékọjá, èyí sì ta ko ohun tó wà lákọsílẹ̀. Àmọ́ Hẹsikáyà gbàdúrà fún wọn pé: “Kí Jèhófà, ẹni rere,+ dárí ji 19 gbogbo ẹni tó ti múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ láti wá Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́,+ ìyẹn Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì wẹ̀ ẹ́ mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà ìjẹ́mímọ́.”+ 20 Jèhófà fetí sí Hẹsikáyà, ó sì dárí ji àwọn èèyàn náà.*
21 Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní Jerúsálẹ́mù fi ọjọ́ méje ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú+ tìdùnnútìdùnnú,+ àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà sì ń yin Jèhófà lójoojúmọ́, wọ́n ń fi àwọn ohun èlò orin wọn kọrin sókè sí Jèhófà.+ 22 Yàtọ̀ síyẹn, Hẹsikáyà bá gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó ń fi ìjìnlẹ̀ òye sin Jèhófà sọ̀rọ̀, ó sì fún wọn níṣìírí.* Ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹun ní àjọyọ̀ náà,+ wọ́n ń rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.
23 Lẹ́yìn náà, gbogbo ìjọ náà pinnu láti fi ọjọ́ méje míì ṣe àjọyọ̀ náà, torí náà, wọ́n fi ọjọ́ méje tó tẹ̀ lé e ṣe é tìdùnnútìdùnnú.+ 24 Hẹsikáyà ọba Júdà wá fi ẹgbẹ̀rún kan (1,000) akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àgùntàn ṣe ọrẹ fún ìjọ náà, àwọn ìjòyè sì fi ẹgbẹ̀rún kan (1,000) akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àgùntàn ṣe ọrẹ fún ìjọ náà;+ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà sì ń ya ara wọn sí mímọ́.+ 25 Gbogbo ìjọ Júdà àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo ìjọ tó wá láti Ísírẹ́lì+ pẹ̀lú àwọn àjèjì+ tó wá láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì àti àwọn tó ń gbé ní Júdà sì ń yọ̀. 26 Ìdùnnú ṣubú layọ̀ ní Jerúsálẹ́mù, torí pé láti ìgbà ayé Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì, irú èyí ò ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.+ 27 Níkẹyìn, àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ àlùfáà dìde dúró, wọ́n sì súre fún àwọn èèyàn náà;+ Ọlọ́run gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì dé ibi mímọ́ tó ń gbé ní ọ̀run.
31 Gbàrà tí wọ́n parí gbogbo èyí, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú Júdà, wọ́n fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́,+ wọ́n gé àwọn òpó òrìṣà lulẹ̀,*+ wọ́n sì wó àwọn ibi gíga+ àti àwọn pẹpẹ+ lulẹ̀ ní gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú Éfúrémù àti Mánásè+ títí wọ́n fi pa wọ́n run pátápátá, lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà sí àwọn ìlú wọn, kálukú pa dà sídìí ohun ìní rẹ̀.
2 Nígbà náà, Hẹsikáyà yan àwọn àlùfáà sí àwùjọ wọn,+ ó sì yan àwọn ọmọ Léfì sí àwùjọ wọn,+ ó yan ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn,+ láti máa rú ẹbọ sísun, kí wọ́n sì máa rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́, kí wọ́n máa dúpẹ́, kí wọ́n sì máa yin Ọlọ́run ní àwọn ẹnubodè tó wà ní àwọn àgbàlá* Jèhófà.+ 3 Ọba fi apá kan lára ẹrù rẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn ẹbọ sísun,+ ìyẹn àwọn ẹbọ òwúrọ̀ àti ti ìrọ̀lẹ́,+ títí kan àwọn ẹbọ sísun fún àwọn Sábáàtì,+ àwọn òṣùpá tuntun+ àti àwọn àjọyọ̀,+ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Jèhófà.
4 Yàtọ̀ síyẹn, ó pàṣẹ fún àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù pé kí wọ́n fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ní apá tó tọ́ sí wọn,+ kí wọ́n lè gbájú mọ́ òfin Jèhófà.* 5 Gbàrà tí ọba pa àṣẹ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkọ́so ọkà, wáìnì tuntun, òróró+ àti oyin pẹ̀lú gbogbo irè oko wá;+ wọ́n mú ìdá mẹ́wàá ohun gbogbo wá ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ.+ 6 Bákan náà, àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti ti Júdà tó ń gbé ní àwọn ìlú Júdà mú ìdá mẹ́wàá àwọn màlúù àti àgùntàn àti ìdá mẹ́wàá àwọn ohun mímọ́ wá,+ àwọn ohun tí a ti yà sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run wọn. Wọ́n mú wọn wá, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì-òkìtì. 7 Ní oṣù kẹta,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ọrẹ wọn jọ ní òkìtì-òkìtì; wọ́n sì parí rẹ̀ ní oṣù keje.+ 8 Nígbà tí Hẹsikáyà àti àwọn ìjòyè wá, tí wọ́n sì rí àwọn òkìtì ọrẹ náà, wọ́n yin Jèhófà, wọ́n sì súre fún àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.
9 Hẹsikáyà béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì nípa àwọn òkìtì náà, 10 Asaráyà olórí àlùfáà ilé Sádókù sì sọ fún un pé: “Láti ìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú ọrẹ wá sínú ilé Jèhófà+ ni àwọn èèyàn náà ti ń jẹ àjẹyó, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ló ṣẹ́ kù, nítorí Jèhófà ti bù kún àwọn èèyàn rẹ̀, ohun tó sì ṣẹ́ kù ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ yìí.”+
11 Ni Hẹsikáyà bá sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣètò àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí*+ ní ilé Jèhófà, wọ́n sì ṣètò wọn. 12 Wọ́n ń mú àwọn ọrẹ wá tinútinú àti ìdá mẹ́wàá+ pẹ̀lú àwọn ohun mímọ́; Konanáyà ọmọ Léfì ni wọ́n fi sídìí gbogbo nǹkan yìí pé kó jẹ́ alábòójútó, Ṣíméì arákùnrin rẹ̀ sì ni igbá kejì. 13 Jéhíélì, Asasáyà, Náhátì, Ásáhélì, Jérímótì, Jósábádì, Élíélì, Isimákáyà, Máhátì àti Bẹnáyà ni àwọn kọmíṣọ́nnà tó ń ran Konanáyà àti Ṣíméì arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọba Hẹsikáyà pa, Asaráyà sì ni alábòójútó ilé Ọlọ́run tòótọ́. 14 Kórè ọmọ Ímúnà, ọmọ Léfì tó jẹ́ aṣọ́bodè lápá ìlà oòrùn+ ló ń bójú tó àwọn ọrẹ àtinúwá+ Ọlọ́run tòótọ́, òun ló sì ń pín ọrẹ tí wọ́n mú wá fún Jèhófà+ àti àwọn ohun mímọ́ jù lọ.+ 15 Àwọn tó wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀ ni Édẹ́nì, Míníámínì, Jéṣúà, Ṣemáyà, Amaráyà àti Ṣẹkanáyà, nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà,+ nínú iṣẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán tí wọ́n ń ṣe, láti máa pín nǹkan lọ́gbọọgba fún àwọn arákùnrin wọn nínú àwọn àwùjọ wọn,+ bí ìpín ẹni ńlá ṣe rí bẹ́ẹ̀ ni ti ẹni kékeré. 16 Èyí jẹ́ àfikún sí ohun tí wọ́n pín fún àwọn ọkùnrin láti ọmọ ọdún mẹ́ta sókè tí orúkọ wọn wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé, tí wọ́n ń wá lójoojúmọ́ láti wá ṣe iṣẹ́ ìsìn ní ilé Jèhófà, kí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ àwùjọ tí wọ́n pín wọn sí.
17 Orúkọ àwọn àlùfáà wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn bí wọ́n ṣe wà ní agbo ilé bàbá wọn,+ bíi ti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè,+ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí wọ́n pín àwùjọ wọn sí.+ 18 Àwọn tó wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn nìyí: gbogbo àwọn ọmọ wọn, àwọn ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin wọn àti ọmọbìnrin wọn, gbogbo ìjọ wọn lápapọ̀, torí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún ohun tó jẹ́ mímọ́ nítorí wọ́n wà ní ipò ẹni tó ṣeé fọkàn tán, 19 títí kan àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì, ìyẹn àwọn àlùfáà tó ń gbé ní àwọn pápá ibi ìjẹko tó yí ìlú wọn ká.+ Ní gbogbo àwọn ìlú náà, wọ́n yan àwọn ọkùnrin tí á máa pín oúnjẹ fún gbogbo ọkùnrin tó wà nínú ìdílé àwọn àlùfáà àti gbogbo ẹni tí orúkọ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé àwọn ọmọ Léfì.
20 Hẹsikáyà ṣe gbogbo nǹkan yìí káàkiri Júdà, ó ń ṣe ohun tó dáa, tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ òdodo níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. 21 Nínú gbogbo iṣẹ́ tó ṣe láti wá Ọlọ́run rẹ̀, bóyá èyí tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́+ tàbí ti Òfin àti àṣẹ, gbogbo ọkàn rẹ̀ ló fi ṣe é, ó sì ṣàṣeyọrí.
32 Lẹ́yìn tí Hẹsikáyà ti fi òtítọ́ ṣe àwọn nǹkan yìí,+ Senakérúbù ọba Ásíríà wá, ó sì ya wọ Júdà. Ó dó ti àwọn ìlú olódi, ó fẹ́ wọlé kí ó sì gbà wọ́n.+
2 Nígbà tí Hẹsikáyà rí i pé Senakérúbù ti dé, tó sì fẹ́ gbéjà ko Jerúsálẹ́mù, 3 lẹ́yìn tó fọ̀rọ̀ lọ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀, ó pinnu láti dí àwọn ìsun omi tó wà lóde ìlú náà pa,+ wọ́n sì ràn án lọ́wọ́. 4 Ọ̀pọ̀ èèyàn kóra jọ, wọ́n sì dí gbogbo ìsun omi pa àti odò tó ń ṣàn gba ilẹ̀ náà kọjá, wọ́n sọ pé: “A ò fẹ́ kí àwọn ọba Ásíríà rí omi lò nígbà tí wọ́n bá wá.”
5 Yàtọ̀ síyẹn, ó rí i dájú pé òun tún gbogbo ògiri tó wó lulẹ̀ mọ, ó sì kọ́ àwọn ilé gogoro lé e lórí, ó tún mọ ògiri míì síta. Bákan náà, ó ṣàtúnṣe Òkìtì*+ tó wà ní Ìlú Dáfídì, ó sì ṣe ohun ìjà* tó pọ̀ gan-an àti àwọn apata. 6 Lẹ́yìn náà, ó yan àwọn olórí ogun lé àwọn èèyàn náà lórí, ó kó wọn jọ sí ojúde ẹnubodè ìlú, ó sì fún wọn níṣìírí,* ó sọ pé: 7 “Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà nítorí ọba Ásíríà+ àti gbogbo ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, torí àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 8 Agbára èèyàn ló gbẹ́kẹ̀ lé,* àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run wa ló wà pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́, kó sì jà fún wa.”+ Ọ̀rọ̀ Hẹsikáyà ọba Júdà sì fún àwọn èèyàn náà lókun.+
9 Lẹ́yìn náà, nígbà tí Senakérúbù ọba Ásíríà wà ní Lákíṣì+ pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀,* ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù, sí Hẹsikáyà ọba Júdà àti sí gbogbo àwọn ará Jùdíà tó wà ní Jerúsálẹ́mù,+ ó sọ pé:
10 “Ohun tí Senakérúbù ọba Ásíríà sọ nìyí, ‘Kí lẹ gbẹ́kẹ̀ lé tí ẹ fi dúró sí Jerúsálẹ́mù nígbà tí a dó tì í?+ 11 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé Hẹsikáyà ń ṣì yín lọ́nà ni, tó fẹ́ kí ìyàn àti òùngbẹ pa yín kú, bó ṣe ń sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa yóò gbà wá lọ́wọ́ ọba Ásíríà”?+ 12 Ṣé kì í ṣe Hẹsikáyà yìí ló mú àwọn ibi gíga+ Ọlọ́run yín* àti àwọn pẹpẹ Rẹ̀ + kúrò, tó wá sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé: “Iwájú pẹpẹ kan ṣoṣo ni kí ẹ ti máa forí balẹ̀, orí rẹ̀ sì ni kí ẹ ti máa mú àwọn ẹbọ yín rú èéfín”?+ 13 Ṣé ẹ kò mọ ohun tí èmi àti àwọn baba ńlá mi ṣe sí gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ míì ni?+ Ṣé àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè gba orílẹ̀-èdè wọn lọ́wọ́ mi ni?+ 14 Èwo nínú gbogbo ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi pa run ló gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ mi, tí Ọlọ́run yín á fi lè gbà yín lọ́wọ́ mi?+ 15 Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà fi èyí tàn yín jẹ tàbí kó ṣì yín lọ́nà!+ Ẹ má gbà á gbọ́, nítorí kò sí ọlọ́run orílẹ̀-èdè kankan tàbí ìjọba èyíkéyìí tó gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ mi àti lọ́wọ́ àwọn baba ńlá mi. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti Ọlọ́run yín pé á gbà yín lọ́wọ́ mi!’”+
16 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tiẹ̀ sọ ohun tó jù bẹ́ẹ̀ lọ sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ àti sí Hẹsikáyà ìránṣẹ́ rẹ̀. 17 Ó tún kọ àwọn lẹ́tà+ láti fi pẹ̀gàn Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ àti láti fi sọ̀rọ̀ òdì sí i, ó ní: “Bí àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè kò ṣe gba àwọn èèyàn wọn lọ́wọ́ mi,+ bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run Hẹsikáyà kò ní gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ mi.” 18 Wọ́n gbóhùn sókè, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè àwọn Júù sí àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù tó wà lórí ògiri, láti dẹ́rù bà wọ́n kí wọ́n sì kó jìnnìjìnnì bá wọn, kí wọ́n lè gba ìlú náà.+ 19 Wọ́n sọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run Jerúsálẹ́mù bí wọ́n ṣe sọ̀rọ̀ sí àwọn ọlọ́run ará ayé, tí wọ́n jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn. 20 Àmọ́ Ọba Hẹsikáyà àti wòlíì Àìsáyà+ ọmọ Émọ́ọ̀sì kò dákẹ́ àdúrà lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì ń ké pe Ọlọ́run lókè ọ̀run pé kó ran àwọn lọ́wọ́.+
21 Lẹ́yìn náà, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan, ó sì pa gbogbo jagunjagun tó lákíkanjú + àti àwọn aṣáájú pẹ̀lú àwọn olórí nínú ibùdó ọba Ásíríà, tó fi di pé ìtìjú ló fi pa dà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀. Nígbà tó yá, ó wọ ilé* ọlọ́run rẹ̀, ibẹ̀ ni àwọn kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ti fi idà pa á.+ 22 Bí Jèhófà ṣe gba Hẹsikáyà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù lọ́wọ́ Senakérúbù ọba Ásíríà nìyẹn àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn yòókù, ó sì fún wọn ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó yí wọn ká. 23 Ọ̀pọ̀ èèyàn mú ẹ̀bùn wá fún Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì mú àwọn ohun iyebíye wá fún Hẹsikáyà ọba Júdà,+ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè sì ń bọ̀wọ̀ fún un gidigidi lẹ́yìn náà.
24 Ní àkókò náà, Hẹsikáyà ṣàìsàn dé ojú ikú, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà.+ Ọlọ́run dá a lóhùn, ó sì fún un ní àmì kan.*+ 25 Àmọ́ Hẹsikáyà kò fi hàn pé òun mọyì ohun rere tó rí gbà, nítorí ìgbéraga ti wọ̀ ọ́ lẹ́wù, èyí sì fa ìbínú Ọlọ́run wá sórí rẹ̀ àti sórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù. 26 Àmọ́, Hẹsikáyà rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ìgbéraga ọkàn rẹ̀ kúrò,+ òun àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, ìbínú Jèhófà kò sì wá sórí wọn ní ìgbà ayé Hẹsikáyà.+
27 Hẹsikáyà wá ní ọrọ̀ tó pọ̀ gan-an àti ògo;+ ó ṣe àwọn ilé ìkẹ́rùsí+ fún ara rẹ̀ láti máa kó fàdákà sí àti wúrà pẹ̀lú àwọn òkúta iyebíye, òróró básámù, àwọn apata àti gbogbo àwọn ohun èlò tó ṣeyebíye. 28 Ó tún kọ́ àwọn ibi tó ń kó nǹkan pa mọ́ sí láti máa kó ọkà àti wáìnì tuntun pẹ̀lú òróró sínú wọn, bákan náà ó kọ́ àwọn ilé ẹran fún onírúurú ẹran ọ̀sìn àti fún àwọn agbo ẹran. 29 Ó tún kọ́ àwọn ìlú fún ara rẹ̀, ó sì ní ọ̀pọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran pẹ̀lú ọ̀wọ́ ẹran, nítorí Ọlọ́run fún un ní ohun ìní tó pọ̀ gan-an. 30 Hẹsikáyà ló dí orísun omi+ Gíhónì+ tó wà lápá òkè pa, ó sì darí rẹ̀ tààràtà lọ sí ìwọ̀ oòrùn Ìlú Dáfídì.+ Hẹsikáyà ṣàṣeyọrí nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. 31 Àmọ́ nígbà tí wọ́n rán àwọn agbẹnusọ àwọn olórí Bábílónì sí i láti béèrè àmì*+ tó wáyé ní ilẹ̀ náà,+ Ọlọ́run tòótọ́ fi í sílẹ̀ láti dán an wò,+ kó lè mọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.+
32 Ní ti ìyókù ìtàn Hẹsikáyà àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó fi hàn,+ wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú ìran wòlíì Àìsáyà,+ ọmọ Émọ́ọ̀sì, nínú Ìwé Àwọn Ọba Júdà àti Ísírẹ́lì.+ 33 Níkẹyìn, Hẹsikáyà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín síbi ìgòkè tó wà níbi tí wọ́n sin àwọn ọmọ Dáfídì sí;+ gbogbo Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù sì yẹ́ ẹ sí nígbà ìsìnkú rẹ̀. Mánásè ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
33 Ọmọ ọdún méjìlá (12) ni Mánásè+ nígbà tó jọba, ọdún márùndínlọ́gọ́ta (55) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+
2 Ó ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, torí pé ó ń ṣe àwọn ohun ìríra bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 3 Ó tún àwọn ibi gíga kọ́, èyí tí Hẹsikáyà bàbá rẹ̀ ti wó lulẹ̀,+ ó mọ àwọn pẹpẹ fún Báálì, ó sì ṣe àwọn òpó òrìṣà.* Ó forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.+ 4 Ó tún mọ àwọn pẹpẹ sí ilé Jèhófà,+ níbi tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé: “Inú Jerúsálẹ́mù ni orúkọ mi yóò máa wà títí láé.”+ 5 Ó mọ àwọn pẹpẹ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run sí àgbàlá méjì nínú ilé Jèhófà.+ 6 Ó sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná+ ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù;+ ó ń pidán,+ ó ń woṣẹ́, ó ń ṣe oṣó, ó sì yan àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́.+ Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.
7 Ó gbé ère gbígbẹ́ tó ṣe wá sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ ilé tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀ fún Dáfídì àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Inú ilé yìí àti ní Jerúsálẹ́mù, tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ni màá fi orúkọ mi sí títí láé.+ 8 Mi ò tún ní ṣí ẹsẹ̀ Ísírẹ́lì kúrò lórí ilẹ̀ tí mo yàn fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọ́n bá ṣáà ti rí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn, ìyẹn gbogbo Òfin, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ látọwọ́ Mósè.” 9 Mánásè ń ṣi Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù lọ́nà nìṣó, ó ń mú kí wọ́n ṣe ohun tó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa run kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
10 Jèhófà bá Mánásè àti àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ títí, àmọ́ wọn ò gbọ́.+ 11 Nítorí náà, Jèhófà mú kí àwọn olórí ọmọ ogun ọba Ásíríà wá gbéjà kò wọ́n, wọ́n fi ìwọ̀ mú Mánásè,* wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é, wọ́n sì mú un lọ sí Bábílónì. 12 Nínú ìdààmú tó bá a, ó bẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pé kó ṣíjú àánú wo òun,* ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀. 13 Ó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sì mú kí àánú ṣe Ọlọ́run, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, ó sì mú un pa dà sí Jerúsálẹ́mù sí ipò ọba rẹ̀.+ Mánásè sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.+
14 Lẹ́yìn náà, ó mọ ògiri ẹ̀yìn òde sí Ìlú Dáfídì+ lápá ìwọ̀ oòrùn Gíhónì+ ní àfonífojì títí dé Ẹnubodè Ẹja,+ ó mọ ọ́n yí ká dé Ófélì,+ ó sì mú kí ó ga gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ó yan àwọn olórí ọmọ ogun sí gbogbo àwọn ìlú olódi ní Júdà. 15 Lẹ́yìn ìyẹn, ó mú àwọn ọlọ́run àjèjì àti ère òrìṣà kúrò ní ilé Jèhófà + àti gbogbo àwọn pẹpẹ tó mọ sí òkè ilé Jèhófà+ àti sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ní kí wọ́n kó wọn dà nù sí ẹ̀yìn òde ìlú. 16 Ó tún ṣètò pẹpẹ Jèhófà,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ àti àwọn ẹbọ ìdúpẹ́+ lórí rẹ̀, ó sì sọ fún Júdà pé kí wọ́n máa sin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 17 Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ lórí àwọn ibi gíga, àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run wọn nìkan ni wọ́n ń rúbọ sí.
18 Ní ti ìyókù ìtàn Mánásè àti àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwọn aríran tí wọ́n bá a sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú ìtàn àwọn ọba Ísírẹ́lì. 19 Bákan náà, àdúrà rẹ̀+ àti bí Ọlọ́run ṣe gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti ìwà àìṣòótọ́ rẹ̀,+ àwọn ibi tó kọ́ ibi gíga sí, tó sì gbé àwọn òpó òrìṣà*+ àti àwọn ère gbígbẹ́ sí kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àwọn aríran rẹ̀. 20 Níkẹyìn, Mánásè sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí ilé rẹ̀; Ámọ́nì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+
21 Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ámọ́nì+ nígbà tó jọba, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ 22 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, bí Mánásè bàbá rẹ̀ ti ṣe;+ Ámọ́nì rúbọ sí gbogbo àwọn ère gbígbẹ́ tí Mánásè bàbá rẹ̀ ṣe,+ ó sì ń sìn wọ́n. 23 Àmọ́ kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà+ bí Mánásè bàbá rẹ̀ ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;+ kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Ámọ́nì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀. 24 Níkẹyìn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn,+ wọ́n sì pa á nínú ilé rẹ̀. 25 Àmọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tó dìtẹ̀ mọ́ Ọba Ámọ́nì,+ wọ́n sì fi Jòsáyà+ ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀.
34 Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni Jòsáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ 2 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, ó rìn ní àwọn ọ̀nà Dáfídì baba ńlá rẹ̀, kò sì yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.
3 Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀, nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀;+ ní ọdún kejìlá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ibi gíga+ àti àwọn òpó òrìṣà* àti àwọn ère gbígbẹ́+ pẹ̀lú àwọn ère onírin* kúrò ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+ 4 Láfikún sí i, wọ́n wó pẹpẹ àwọn Báálì lulẹ̀ níṣojú rẹ̀, ó sì gé àwọn pẹpẹ tùràrí tó wà lókè orí wọn lulẹ̀. Ó tún fọ́ àwọn òpó òrìṣà* àti àwọn ère gbígbẹ́ pẹ̀lú àwọn ère onírin* sí wẹ́wẹ́, ó lọ̀ wọ́n lẹ́búlẹ́bú, ó sì wọ́n ekuru wọn sórí sàréè àwọn tó ń rúbọ sí wọn tẹ́lẹ̀.+ 5 Ó sun egungun àwọn àlùfáà lórí àwọn pẹpẹ wọn.+ Bí ó ṣe fọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù mọ́ nìyẹn.
6 Ní àwọn ìlú Mánásè, Éfúrémù,+ Síméónì àti títí dé Náfútálì, ní àwọn ibi tó ti di àwókù tó yí wọn ká, 7 ó wó àwọn pẹpẹ, ó fọ́ àwọn òpó òrìṣà* àti àwọn ère gbígbẹ́ túútúú,+ ó sì lọ̀ wọ́n lẹ́búlẹ́bú; ó gé gbogbo àwọn pẹpẹ tùràrí lulẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ lẹ́yìn náà, ó pa dà sí Jerúsálẹ́mù.
8 Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba rẹ̀, nígbà tó ti fọ ilẹ̀ náà àti tẹ́ńpìlì* náà mọ́, ó rán Ṣáfánì + ọmọ Asaláyà àti Maaseáyà olórí ìlú náà àti Jóà ọmọ Jóáhásì akọ̀wé ìrántí láti lọ tún ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ṣe.+ 9 Wọ́n wá sọ́dọ̀ Hilikáyà àlùfáà àgbà, wọ́n sì fún un ní owó tí àwọn èèyàn mú wá sí ilé Ọlọ́run, èyí tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ aṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ Mánásè àti Éfúrémù àti lọ́wọ́ gbogbo ìyókù Ísírẹ́lì,+ títí kan Júdà, Bẹ́ńjámínì àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù. 10 Lẹ́yìn náà, wọ́n kó o fún àwọn tí wọ́n yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ ilé Jèhófà. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Jèhófà sì lò ó láti mú ilé náà bọ̀ sípò àti láti tún un ṣe. 11 Wọ́n kó o fún àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn kọ́lékọ́lé láti fi ra òkúta gbígbẹ́ àti àwọn ẹ̀là gẹdú láti fi ṣe àwọn agbóhunró àti àwọn ìtì igi tí wọ́n á fi kọ́ àwọn ilé tí àwọn ọba Júdà ti jẹ́ kó di àwókù.+
12 Àwọn ọkùnrin náà fi òótọ́ inú ṣe iṣẹ́ náà.+ Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n yàn láti jẹ́ alábòójútó wọn ni Jáhátì àti Ọbadáyà látinú àwọn ọmọ Mérárì+ àti Sekaráyà pẹ̀lú Méṣúlámù látinú àwọn ọmọ Kóhátì.+ Àwọn ọmọ Léfì, tí gbogbo wọn jẹ́ olórin tó mọṣẹ́ orin,+ 13 ló ń mójú tó àwọn lébìrà,* àwọn sì tún ni alábòójútó gbogbo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà ní onírúurú ẹ̀ka; àwọn kan lára àwọn ọmọ Léfì sì jẹ́ akọ̀wé, aláṣẹ àti aṣọ́bodè.+
14 Nígbà tí wọ́n ń kó owó táwọn èèyàn mú wá sí ilé Jèhófà jáde,+ àlùfáà Hilikáyà rí ìwé Òfin+ tí Jèhófà fún wọn nípasẹ̀* Mósè.+ 15 Torí náà, Hilikáyà sọ fún Ṣáfánì akọ̀wé pé: “Mo ti rí ìwé Òfin ní ilé Jèhófà.” Ni Hilikáyà bá fún Ṣáfánì ní ìwé náà. 16 Ṣáfánì mú ìwé náà wá sọ́dọ̀ ọba, ó sì sọ fún un pé: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe gbogbo ohun tí a yàn fún wọn. 17 Wọ́n ti kó owó tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà, wọ́n sì ti kó o fún àwọn ọkùnrin tí a yàn àti àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà.” 18 Ṣáfánì akọ̀wé tún sọ fún ọba pé: “Ìwé kan wà tí àlùfáà Hilikáyà fún mi.”+ Ṣáfánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á níwájú ọba.+
19 Gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú Òfin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya.+ 20 Ọba wá pa àṣẹ yìí fún Hilikáyà, Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì, Ábídónì ọmọ Míkà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáyà ìránṣẹ́ ọba pé: 21 “Ẹ lọ bá èmi àti àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì àti ní Júdà wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a rí yìí; nítorí ìbínú Jèhófà tó máa tú jáde sórí wa pọ̀ gan-an torí àwọn baba ńlá wa kò pa ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́, wọn ò ṣe gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé yìí.”+
22 Torí náà, Hilikáyà àti àwọn tí ọba rán, lọ sọ́dọ̀ wòlíì obìnrin+ tó ń jẹ́ Húlídà. Òun ni ìyàwó Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háhásì, ẹni tó ń bójú tó ibi tí wọ́n ń kó aṣọ sí. Ó ń gbé ní Apá Kejì Jerúsálẹ́mù; wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀.+ 23 Ó sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ẹ sọ fún ọkùnrin tó rán yín wá sọ́dọ̀ mi pé: 24 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Màá mú àjálù bá ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀,+ ìyẹn gbogbo ègún tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé+ tí wọ́n kà níwájú ọba Júdà. 25 Nítorí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run míì láti fi gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn mú mi bínú,+ ìbínú mi máa tú jáde bí iná sórí ibí yìí, kò sì ní ṣeé pa.’”+ 26 Àmọ́, ní ti ọba Júdà tó rán yín pé kí ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́,+ 27 nítorí pé ọlọ́kàn tútù ni ọ́,* tí o rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run bí o ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi, tí o fa aṣọ rẹ ya, tí o sì sunkún níwájú mi, èmi náà ti gbọ́ ohun tí o sọ,+ ni Jèhófà wí. 28 Ìdí nìyẹn tí màá fi kó ọ jọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ,* a ó tẹ́ ọ sínú sàréè rẹ ní àlàáfíà, ojú rẹ ò ní rí gbogbo àjálù tí màá mú bá ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀.’”’”+
Lẹ́yìn náà, wọ́n mú èsì náà wá fún ọba. 29 Nígbà náà, ọba ránṣẹ́, ó sì pe gbogbo àwọn àgbààgbà Júdà àti Jerúsálẹ́mù jọ.+ 30 Lẹ́yìn náà, ọba lọ sí ilé Jèhófà pẹ̀lú gbogbo èèyàn Júdà, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn gbogbo àwọn èèyàn náà, ẹni kékeré àti ẹni ńlá. Ó ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé májẹ̀mú tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà sí wọn létí.+ 31 Ọba dúró sí àyè rẹ̀, ó sì dá májẹ̀mú*+ níwájú Jèhófà pé gbogbo ọkàn àti gbogbo ara* ni òun á máa fi tẹ̀ lé Jèhófà,+ òun á sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀, láti máa ṣe ohun tí májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí sọ.+ 32 Yàtọ̀ síyẹn, ó mú kí gbogbo àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Bẹ́ńjámínì fara mọ́ ọn. Àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù sì ṣe ohun tí májẹ̀mú Ọlọ́run sọ, ìyẹn Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+ 33 Lẹ́yìn ìyẹn, Jòsáyà mú gbogbo àwọn ohun ìríra* kúrò ní gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ ó sì mú kí gbogbo àwọn tó wà ní Ísírẹ́lì máa sin Jèhófà Ọlọ́run wọn. Ní gbogbo ọjọ́ ayé* rẹ̀, wọn ò pa dà lẹ́yìn Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.
35 Jòsáyà ṣe Ìrékọjá+ kan fún Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì pa ẹran Ìrékọjá náà + ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní.+ 2 Ó yan àwọn àlùfáà sẹ́nu iṣẹ́ wọn, ó sì fún wọn ní ìṣírí pé kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ilé Jèhófà.+ 3 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún àwọn ọmọ Léfì, àwọn olùkọ́ gbogbo Ísírẹ́lì,+ tí wọ́n jẹ́ mímọ́ sí Jèhófà pé: “Ẹ gbé Àpótí mímọ́ sínú ilé tí Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì kọ́;+ ẹ ò ní máa gbé e lé èjìká yín mọ́.+ Ní báyìí, ẹ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà Ọlọ́run yín àti àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì. 4 Ẹ ṣètò ara yín sí àwùjọ-àwùjọ nínú agbo ilé yín, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Dáfídì+ ọba Ísírẹ́lì àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ kọ sílẹ̀.+ 5 Ẹ dúró ní ibi mímọ́ ní àwùjọ tí wọ́n pín agbo ilé àwọn arákùnrin yín sí, ìyẹn ìyókù àwọn èèyàn náà,* kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan wọn ní àwùjọ kan látinú ìdílé àwọn ọmọ Léfì tó máa ṣiṣẹ́ fún wọn. 6 Kí ẹ pa ẹran Ìrékọjá,+ kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì múra sílẹ̀ de àwọn arákùnrin yín kí wọ́n lè ṣe ohun tí Jèhófà gbẹnu Mósè sọ.”
7 Jòsáyà fún àwọn èèyàn náà ní agbo ẹran, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti akọ ọmọ ewúrẹ́, láti fi ṣe ẹran Ìrékọjá fún gbogbo àwọn tó wá, àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000), ó tún fi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) màlúù kún un. Inú ohun ìní ọba ni àwọn nǹkan yìí ti wá.+ 8 Àwọn ìjòyè rẹ̀ tún fún àwọn èèyàn náà àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì ní ọrẹ àtinúwá. Hilikáyà,+ Sekaráyà àti Jéhíélì, àwọn aṣáájú ilé Ọlọ́run tòótọ́, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (2,600) ẹran Ìrékọjá àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) màlúù. 9 Konanáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ Ṣemáyà àti Nétánélì pẹ̀lú Haṣabáyà, Jéélì àti Jósábádì, àwọn olórí àwọn ọmọ Léfì, fún àwọn ọmọ Léfì ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ẹran Ìrékọjá àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) màlúù.
10 Wọ́n múra iṣẹ́ ìsìn náà sílẹ̀, àwọn àlùfáà dúró sí àyè wọn, àwọn ọmọ Léfì sì dúró ní àwọn àwùjọ wọn,+ gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe pa á láṣẹ. 11 Wọ́n pa àwọn ẹran Ìrékọjá,+ àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lára wọn,+ àwọn ọmọ Léfì sì ń bó awọ àwọn ẹran náà.+ 12 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣètò àwọn ẹbọ sísun kí wọ́n lè pín wọn fún ìyókù àwọn èèyàn náà, àwọn tí wọ́n wà ní àwùjọ-àwùjọ nínú agbo ilé bàbá wọn, kí wọ́n lè mú wọn wá fún Jèhófà bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Mósè; wọ́n sì ṣe ohun kan náà ní ti àwọn màlúù náà. 13 Wọ́n se* ẹran Ìrékọjá lórí iná gẹ́gẹ́ bí àṣà;+ wọ́n sì se àwọn ẹran mímọ́ nínú àwọn ìkòkò àti àwọn ìkòkò irin pẹ̀lú àwọn páànù, lẹ́yìn náà, wọ́n gbé e wá kíákíá fún gbogbo ìyókù àwọn èèyàn náà. 14 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣètò nǹkan sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà, nítorí pé àwọn àlùfáà, ìyẹn àwọn ọmọ Áárónì, ń rú ẹbọ sísun àti àwọn apá tó lọ́ràá títí ilẹ̀ fi ṣú, torí náà, àwọn ọmọ Léfì ṣètò nǹkan sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Áárónì.
15 Àwọn akọrin, ìyẹn àwọn ọmọ Ásáfù,+ wà ní àyè wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dáfídì+ àti Ásáfù+ àti Hémánì pẹ̀lú Jédútúnì+ aríran ọba; àwọn aṣọ́bodè sì wà ní ẹnubodè kọ̀ọ̀kan.+ Kò sí ìdí fún wọn láti kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn, nítorí pé àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Léfì ti ṣètò nǹkan sílẹ̀ fún wọn. 16 Torí náà, wọ́n ṣètò gbogbo iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní ọjọ́ yẹn kí wọ́n lè ṣe Ìrékọjá náà,+ kí wọ́n sì rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọba Jòsáyà pa.+
17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ fi ọjọ́ méje ṣe Ìrékọjá àti Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú ní àkókò yẹn.+ 18 Wọn ò ṣe irú Ìrékọjá bẹ́ẹ̀ rí ní Ísírẹ́lì láti ìgbà ayé wòlíì Sámúẹ́lì; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìkankan lára àwọn ọba Ísírẹ́lì tó ṣe irú Ìrékọjá tí Jòsáyà ṣe+ pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Júdà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù. 19 Wọ́n ṣe Ìrékọjá yìí ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jòsáyà.
20 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan yìí, tí Jòsáyà ti múra tẹ́ńpìlì* náà sílẹ̀, Nékò+ ọba Íjíbítì wá jà ní Kákémíṣì lẹ́gbẹ̀ẹ́ Yúfírétì. Ni Jòsáyà bá jáde lọ dojú kọ ọ́.+ 21 Torí náà, ó rán àwọn òjíṣẹ́ sí Jòsáyà, ó ní: “Kí ló kàn ọ́ nínú ọ̀ràn yìí, ìwọ ọba Júdà? Ìwọ kọ́ ni mo wá bá jà lónìí, ilé mìíràn ni mo wá bá, Ọlọ́run sì sọ fún mi pé kí n ṣe kíá. Torí náà, fún àǹfààní ara rẹ, má dojú kọ Ọlọ́run, ẹni tó wà pẹ̀lú mi, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa pa ọ́ run.” 22 Síbẹ̀, Jòsáyà kò pa dà lẹ́yìn rẹ̀, ńṣe ló para dà+ láti lọ bá a jà, kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ Nékò, èyí tó wá láti ẹnu Ọlọ́run. Torí náà, ó wá jà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mẹ́gídò.+
23 Àwọn tafàtafà ta Ọba Jòsáyà lọ́fà, ọba sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ gbé mi kúrò níbí, torí mo ti fara gbọgbẹ́ gan-an.” 24 Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbé e kúrò nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, wọ́n sì fi kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ kejì gbé e wá sí Jerúsálẹ́mù. Bó ṣe kú nìyẹn, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba ńlá rẹ̀,+ gbogbo Júdà àti Jerúsálẹ́mù sì ṣọ̀fọ̀ Jòsáyà. 25 Jeremáyà+ sun rárà fún Jòsáyà, gbogbo akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ sì ń sọ nípa Jòsáyà nínú orin arò* wọn títí di òní yìí; wọ́n pinnu pé kí wọ́n máa kọ àwọn orin náà ní Ísírẹ́lì, wọ́n sì wà lákọsílẹ̀ nínú àwọn orin arò.
26 Ní ti ìyókù ìtàn Jòsáyà àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó fi hàn, bó ṣe ń tẹ̀ lé ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Jèhófà, 27 títí kan àwọn ohun tó ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà.+
36 Àwọn èèyàn ilẹ̀ náà mú Jèhóáhásì+ ọmọ Jòsáyà, wọ́n sì fi í jọba ní Jerúsálẹ́mù ní ipò bàbá rẹ̀.+ 2 Ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23) ni Jèhóáhásì nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. 3 Àmọ́, ọba Íjíbítì lé e kúrò lórí oyè ní Jerúsálẹ́mù, ó sì bu owó ìtanràn ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì* fàdákà àti tálẹ́ńtì wúrà kan lé ilẹ̀ náà.+ 4 Yàtọ̀ síyẹn, ọba Íjíbítì fi Élíákímù arákùnrin Jèhóáhásì jọba lórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Jèhóákímù; ṣùgbọ́n Nékò+ mú Jèhóáhásì arákùnrin rẹ̀, ó sì mú un wá sí Íjíbítì.+
5 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Jèhóákímù+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.+ 6 Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì wá dojú kọ ọ́, kó lè fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é láti mú un lọ sí Bábílónì.+ 7 Nebukadinésárì kó lára àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà lọ sí Bábílónì, ó sì kó wọn sínú ààfin rẹ̀ ní Bábílónì.+ 8 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóákímù àti àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti nǹkan búburú tí a mọ̀ nípa rẹ̀, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà; Jèhóákínì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+
9 Ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni Jèhóákínì+ nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù; ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà.+ 10 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún,* Ọba Nebukadinésárì ní kí wọ́n lọ mú un wá sí Bábílónì+ pẹ̀lú àwọn ohun iyebíye tó wà ní ilé Jèhófà.+ Bákan náà, ó fi Sedekáyà arákùnrin bàbá rẹ̀ jọba lórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+
11 Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni Sedekáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ 12 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú wòlíì Jeremáyà,+ ẹni tó ń sọ ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un. 13 Ó tún ṣọ̀tẹ̀ sí Ọba Nebukadinésárì,+ ẹni tó mú kó fi Ọlọ́run búra, ó ya olórí kunkun* àti ọlọ́kàn líle, ó kọ̀, kò yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 14 Gbogbo olórí àwọn àlùfáà àti àwọn èèyàn náà hùwà àìṣòótọ́ tó bùáyà, wọ́n ń ṣe àwọn ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè ń ṣe, wọ́n sì sọ ilé Jèhófà di ẹlẹ́gbin,+ èyí tó ti yà sí mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.
15 Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ń kìlọ̀ fún wọn léraléra, nítorí pé àánú àwọn èèyàn rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀ ń ṣe é. 16 Ṣùgbọ́n wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín,+ wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí,+ wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,+ títí ìbínú Jèhófà fi ru sí àwọn èèyàn rẹ̀,+ tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.
17 Nítorí náà, ó gbé ọba àwọn ará Kálídíà+ dìde sí wọn, ẹni tó fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn+ nínú ibi mímọ́ wọn;+ kò ṣàánú ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin,* arúgbó tàbí aláàárẹ̀.+ Ohun gbogbo ni Ọlọ́run fi lé e lọ́wọ́.+ 18 Gbogbo àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́, ńlá àti kékeré pẹ̀lú àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ìṣúra ọba àti ti àwọn ìjòyè rẹ̀, gbogbo rẹ̀ pátá ló kó wá sí Bábílónì.+ 19 Ó sun ilé Ọlọ́run tòótọ́ kanlẹ̀,+ ó wó ògiri Jerúsálẹ́mù lulẹ̀,+ ó sun gbogbo àwọn ilé gogoro tó láàbò, ó sì ba gbogbo ohun tó ṣeyebíye jẹ́.+ 20 Ó mú àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ idà lẹ́rú, ó kó wọn lọ sí Bábílónì,+ wọ́n sì di ìránṣẹ́ òun+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí di ìgbà tí ìjọba* Páṣíà fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso,+ 21 kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà sọ lè ṣẹ,+ títí ilẹ̀ náà fi san àwọn sábáàtì rẹ̀ tán.+ Ní gbogbo ọjọ́ tó fi wà ní ahoro, ó ń pa sábáàtì rẹ̀ mọ́, kí àádọ́rin (70) ọdún lè pé.+
22 Ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Páṣíà, kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà+ sọ lè ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí Kírúsì ọba Páṣíà jí láti kéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì tún kọ ọ́ sílẹ̀+ pé: 23 “Ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà sọ nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé,+ ó sì pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù, tó wà ní Júdà.+ Ta ni nínú yín tó jẹ́ èèyàn rẹ̀? Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì lọ síbẹ̀.’”+
Tàbí “máa ń wádìí lọ́dọ̀ Rẹ̀ níbẹ̀.”
Ní Héb., “tí màá fi máa jáde níwájú àwọn èèyàn yìí, tí màá sì fi máa wọlé.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ọ̀pọ̀ ọjọ́.”
Tàbí “àwọn agẹṣin.”
Tàbí “àwọn agẹṣin.”
Tàbí kó jẹ́, “láti Íjíbítì àti Kúè; àwọn oníṣòwò ọba á rà wọ́n láti Kúè,” ó lè jẹ́ pé Sìlíṣíà ló ń tọ́ka sí.
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “láti máa ru ẹrù.”
Tàbí “ààfin.”
Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.
Kọ́ọ̀ kan jẹ́ Lítà 220. Wo Àfikún B14.
Tàbí “wíìtì.”
Báàtì kan jẹ́ Lítà 22 (gálọ́ọ̀nù 5.81). Wo Àfikún B14.
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “láti máa ru ẹrù.”
Ìgbọ̀nwọ́ tí wọ́n máa ń lò jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5), àmọ́ àwọn kan sọ pé “ìwọ̀n tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀” tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ gígùn tó jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 51.8 (ínǹṣì 20.4). Wo Àfikún B14.
Tàbí “Gọ̀bì.”
Tàbí “ó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ lára fífẹ̀ ilé náà.”
Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ kan pè é ní “ọgọ́fà (120),” àmọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtàwọn ìtumọ̀ míì pè é ní “ogún (20) ìgbọ̀nwọ́.
Ní Héb., “ilé.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14
Ní Héb., “ilé.”
Ìyẹn, sápá Ibi Mímọ́.
Tàbí “gúúsù.”
Tàbí “àríwá.”
Ó túmọ̀ sí “Kí Ó [ìyẹn, Jèhófà] Fìdí Rẹ̀ Múlẹ̀ Gbọn-in.”
Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Nínú Okun.”
Tàbí “agbada ńlá.”
Nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 7.4 (ínǹṣì 2.9.). Wo Àfikún B14.
Báàtì kan jẹ́ Lítà 22 (gálọ́ọ̀nù 5.81). Wo Àfikún B14.
Tàbí “gbàgede.”
Tàbí “kẹ̀kẹ́ omi.”
Tàbí “ẹ̀mú.”
Ìyẹn, Àjọyọ̀ Àtíbàbà.
Tàbí “Àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì.”
Tàbí “aro.”
Ní Héb., “ọmọ rẹ, tó máa jáde láti abẹ́ rẹ.”
Tàbí “gbàgede.”
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Tàbí “tí ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ sì gégùn-ún fún un.” Ìyẹn, ìbúra tó ní ègún nínú gẹ́gẹ́ bí ìyà tó máa jẹ ẹni tó bá búra èké tàbí tó dalẹ̀.
Ní Héb., “ègún.”
Ní Héb., “ègún.”
Ní Héb., “olódodo.”
Tàbí “fìyà jẹ wọ́n.”
Tàbí “tata.”
Ní Héb., “ní ilẹ̀ àwọn ẹnubodè rẹ̀.”
Tàbí “ohun tó gbọ́ nípa rẹ.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “nípa.”
Ní Héb., “má ṣe yí ojú ẹni àmì òróró rẹ kúrò.”
Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí àwọn ọmọ Léfì.
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Ọjọ́ tó tẹ̀ lé àjọyọ̀ náà tàbí ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún.
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “àfipòwe.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Tàbí “ó tún Tádímórì ní aginjù kọ́.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “lẹ́sẹẹsẹ; parí.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “àwọn àlọ́.”
Tàbí “ẹgbẹ́ abánirìn.”
Ní Héb., “fara pa mọ́.”
Ní Héb., “kò sí ẹ̀mí kankan mọ́ nínú rẹ̀.”
Tàbí “ọ̀rọ̀.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ààfin.”
Tàbí kó jẹ́, “ní àfikún sí àwọn ẹ̀bùn tí iye rẹ̀ jẹ́.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.
Mínà kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jẹ́ gíráàmù 570. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “wá ojú.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.
Tàbí “àwọn agẹṣin.”
Ìyẹn, odò Yúfírétì.
Tàbí “tó nira.”
Tàbí “àwọn àgbààgbà.”
Tàbí “àwọn àgbààgbà.”
Tàbí “ìránṣẹ́.”
Tàbí “ọmọńdinrín mi.”
Tàbí “àwọn àgbààgbà.”
Ní Héb., “àgọ́.”
Ní Héb., “àṣàyàn jagunjagun.”
Tàbí “mọ odi.”
Ní Héb., “àwọn ewúrẹ́.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “fọ́n lára àwọn ọmọ rẹ̀ ká.”
Ní Héb., “àwọn ìjọba.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “àwọn sárésáré.”
Ní Héb., “àṣàyàn jagunjagun.”
Ní Héb., “àṣàyàn ọkùnrin.”
Ìyẹn, májẹ̀mú tó wà títí lọ, tí kò sì ní yí pa dà.
Ní Héb., “tó bá fi akọ ọmọ màlúù kan àti àgbò méje kún ọwọ́ rẹ̀.”
Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.
Ní Héb., “àṣàyàn ọkùnrin.”
Ní Héb., “gbára lé.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Tàbí “àlàyé.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì.”
Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.
Ní Héb., “wọ́n mọ bí a ṣe ń fi okùn sí ọrun.”
Ní Héb., “gbára lé.”
Ní Héb., “Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni.”
Ní Héb., “kò sí àlàáfíà fún ẹni tó ń jáde lọ tàbí fún ẹni tó ń wọlé bọ̀.”
Ní Héb., “kí ọwọ́ yín wálẹ̀.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “ìyáàfin.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ọkàn Ásà pé pérépéré.”
Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”
Tàbí “mọ odi; tún Rámà kọ́.”
Tàbí “sí ìpínlẹ̀.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “Májẹ̀mú.”
Tàbí “májẹ̀mú.”
Tàbí “mímọ odi; títún Rámà kọ́.”
Tàbí “mọ odi; tún Gébà kọ́.”
Ní Héb., “gbára lé.”
Ní Héb., “gbára lé.”
Tàbí “ìtìlẹ́yìn.”
Ní Héb., “sí ilé àbà.”
Ó ṣe kedere pé, wọn ò finá sun òkú Ásà, àwọn èròjà ni wọ́n finá sun.
Ní Héb., “ó rìn nínú àṣẹ rẹ̀.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “owó òde.”
Ní Héb., “ọrun.”
Tàbí “fi ọ̀pọ̀ àgùntàn àti màlúù rúbọ.”
Tàbí “bẹ̀ ẹ́.”
Tàbí “ti.”
Tàbí “áńgẹ́lì.”
Tàbí “ta ọfà rẹ̀ láìfojú sun nǹkan kan.”
Ní Héb., “nínú ibùdó.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ní àlàáfíà.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ọkàn rẹ ti múra tán.”
Tàbí “ọkàn tó pa pọ̀.”
Tàbí “pẹ̀lú ohun rere.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn Méúnì.”
Ó ṣe kedere pé Òkun Òkú ni.
Ní Héb., “yíjú sí wíwá.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
Tàbí “kí ẹ sì rí bí Jèhófà á ṣe gbà yín là.”
Tàbí “kí ẹ lè fara dà á.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “fi ìbùkún fún.”
Ó túmọ̀ sí “Ìbùkún.”
Ní Héb., “òun á fún Dáfídì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní fìtílà.”
Ní Héb., “ẹ̀mí àwọn Filísínì.”
Tàbí “ààfin.”
Wọ́n tún ń pè é ní Ahasáyà.
Tàbí “àwọn akónilẹ́rù.”
Ní Héb., “ọmọbìnrin.”
Wọ́n pè é ní Asaráyà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan lédè Hébérù.
Tàbí “ó ń ṣàìsàn.”
Ní Héb., “ọmọkùnrin.”
Ní Héb., “ké ilé Áhábù kúrò.”
Ní Héb., “gbogbo èso ìjọba.”
Tàbí “dá májẹ̀mú.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “nígbà tó bá wọlé àti nígbà tó bá jáde.”
Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.
Tàbí “apata ribiti.”
Tàbí “ọṣẹ́.”
Tàbí “dáyádémà.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwé tí Òfin Ọlọ́run wà nínú rẹ̀.
Ní Héb., “òpó rẹ̀.”
Tàbí “fi àmì darí.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Ní Héb., “láti ọwọ́ Dáfídì.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “fi idà pa.”
Tàbí kó jẹ́, “títí gbogbo wọn fi mú wá.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “tí ìbínú fi ru.”
Tàbí “jẹ́rìí láti ta kò wọ́n.”
Ní Héb., “bo.”
Ìyẹn, bàbá Sekaráyà.
Ní Héb., “Nígbà ìyípo ọdún.”
Ìyẹn, àwọn ará Síríà.
Tàbí “pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àrùn.”
Tàbí “ọmọ.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àpọ́nlé ni ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ yìí.
Ní Héb., “ìfilọ́lẹ̀.”
Tàbí “àlàyé.”
Ní Héb., “àṣàyàn jagunjagun.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “jẹ́ ká wojú ara wa.”
Ní Héb., “O.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “àgọ́.”
Wọ́n tún ń pè é ní Ahasáyà.
Nǹkan bíi mítà 178 (ẹsẹ̀ bàtà 584). Wo Àfikún B14.
Tàbí “lábẹ́ àbójútó.”
Tàbí “ààfin.”
Ìyẹn, Amasááyà bàbá rẹ̀.
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “gbẹ́ kòtò omi púpọ̀ jáde,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ látinú àpáta.
Tàbí “ilẹ̀ tó tẹ́jú.”
Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.
Ní Héb., “ọrun.”
Tàbí “ààfin.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Kọ́ọ̀ kan jẹ́ Lítà 220. Wo Àfikún B14.
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “múra.”
Tàbí “ṣe ère dídà.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Gẹ̀hẹ́nà.”
Ní Héb., “ilé.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “ẹ̀sín.”
Tàbí “sinmi.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.
Tàbí “aro.”
Ní Héb., “tí ẹ ti fi nǹkan kún ọwọ́ yín.”
Ní Héb., “ọkàn àwọn ọmọ Léfì dúró ṣánṣán.”
Tàbí “múra iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà sílẹ̀.”
Tàbí “gbogbo ìjọ.”
Tàbí “gbogbo ìjọ.”
Ní Héb., “àwọn sárésáré.”
Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
Ní Héb., “àwọn sárésáré.”
Ní Héb., “láti fún wọn ní ọkàn kan.”
Ní Héb., “wo àwọn èèyàn náà sàn.”
Ní Héb., “sọ̀rọ̀ sí ọkàn wọn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “àwọn ibùdó.”
Tàbí “kí wọ́n lè fi ara wọn fún òfin Jèhófà pátápátá.”
Tàbí “àwọn yàrá ìjẹun.”
Tàbí “Mílò.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “iyẹ̀pẹ̀ tí a kó jọ gègèrè.”
Tàbí “ọṣẹ́.”
Ní Héb., “ó sì sọ̀rọ̀ sí ọkàn wọn.”
Ní Héb., “Apá tó jẹ́ ẹran ara ló wà pẹ̀lú rẹ̀.”
Tàbí “pẹ̀lú gbogbo àwọn ológun rẹ̀ àti ògo rẹ̀.”
Ní Héb., “rẹ̀.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “fi ohun tó máa ṣẹlẹ̀ hàn án.”
Tàbí “ohun tó máa ṣẹlẹ̀.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí kó jẹ́, “wọ́n mú Mánásè ní ibi tó jin kòtò.”
Tàbí “ó tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “àwọn ère dídà.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “àwọn ère dídà.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “ilé.”
Tàbí “àwọn tó ń ru ẹrù.”
Ní Héb., “láti ọwọ́.”
Ní Héb., “ọkàn rẹ rọ̀.”
Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.
Tàbí “tún májẹ̀mú dá.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “àwọn òrìṣà.”
Ní Héb., “Ní gbogbo ọjọ́.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ àwọn èèyàn náà.”
Tàbí kó jẹ́, “yan.”
Ní Héb., “ilé.”
Tàbí “àwọn orin ọ̀fọ̀.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́, ìgbà ìrúwé.
Ní Héb., “mú ọrùn rẹ̀ le.”
Ní Héb., “wúńdíá.”
Tàbí “ipò ọba.”