ÌSÍKÍẸ́LÌ
1 Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin, ọdún ọgbọ̀n, nígbà tí mo wà lẹ́bàá odò Kébárì+ láàárín àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn,+ ọ̀run ṣí sílẹ̀, mo sì rí ìran látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 2 Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù náà, ìyẹn, ọdún karùn-ún tí Ọba Jèhóákínì ti wà ní ìgbèkùn,+ 3 Jèhófà bá Ìsíkíẹ́lì* ọmọ àlùfáà Búúsì sọ̀rọ̀ lẹ́bàá odò Kébárì ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà.+ Ọwọ́ Jèhófà sì wá sórí rẹ̀ níbẹ̀.+
4 Bí mo ṣe ń wò, mo rí i tí ìjì líle+ ń fẹ́ bọ̀ láti àríwá, ìkùukùu* ńlá wà níbẹ̀, iná* sì ń kọ mànà, ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò+ yí i ká, ohun kan sì wà nínú iná náà tó ń tàn yanran bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà.+ 5 Àwọn ohun tó dà bí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ wà nínú rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì rí bí èèyàn. 6 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin.+ 7 Ẹsẹ̀ wọn rí gbọọrọ, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn dà bíi ti ọmọ màlúù, wọ́n sì ń kọ mànà bíi bàbà dídán.+ 8 Wọ́n ní ọwọ́ èèyàn lábẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì ní ojú àti ìyẹ́. 9 Àwọn ìyẹ́ wọn ń kan ara wọn. Wọn kì í yà síbì kankan bí wọ́n ṣe ń lọ; iwájú tààrà ni kálukú wọn ń lọ.+
10 Bí ojú wọn ṣe rí nìyí: Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú èèyàn, ojú kìnnìún+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún, ojú akọ màlúù+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ojú+ idì.+ 11 Bí ojú wọn ṣe rí nìyẹn. Wọ́n na ìyẹ́ apá wọn sókè. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ méjì tó kanra àti ìyẹ́ méjì tó fi bo ara.+
12 Iwájú tààrà ni kálukú wọn ń lọ, ibikíbi tí ẹ̀mí bá darí wọn sí ni wọ́n ń lọ.+ Wọn kì í yà síbì kankan bí wọ́n ṣe ń lọ. 13 Àwọn ẹ̀dá alààyè náà rí bí ẹyin iná tó ń jó, ohun kan tó rí bí ògùṣọ̀ tí iná rẹ̀ mọ́lẹ̀ yòò ń lọ síwá-sẹ́yìn láàárín àwọn ẹ̀dá alààyè náà, mànàmáná sì ń kọ látinú iná náà.+ 14 Bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà ṣe ń lọ tí wọ́n ń bọ̀, lílọ bíbọ̀ wọn dà bíi ti mànàmáná.
15 Bí mo ṣe ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè náà, mo rí àgbá kẹ̀kẹ́ kan lórí ilẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè tó ní ojú mẹ́rin náà.+ 16 Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà àti iṣẹ́ ara wọn ń dán bí òkúta kírísóláítì, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jọra. Iṣẹ́ ara wọn àti bí wọ́n ṣe rí dà bí ìgbà tí àgbá kẹ̀kẹ́ kan wà nínú àgbá kẹ̀kẹ́ míì.* 17 Tí wọ́n bá ń lọ, wọ́n lè lọ sí ibikíbi ní ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin láì ṣẹ́rí pa dà. 18 Àwọn àgbá náà ga débi pé wọ́n ń bani lẹ́rù, ojú sì wà káàkiri ara àgbá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà.+ 19 Tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá ń lọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a lọ pẹ̀lú wọn, tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì gbéra sókè, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà á gbéra sókè.+ 20 Wọ́n á lọ sí ibi tí ẹ̀mí bá darí wọn sí, ìyẹn ibikíbi tí ẹ̀mí náà bá lọ. Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà á gbéra pẹ̀lú wọn, torí ẹ̀mí tó ń darí àwọn ẹ̀dá alààyè náà* tún wà nínú àwọn àgbá náà. 21 Tí wọ́n bá ń lọ, àwọn àgbá náà máa ń tẹ̀ lé wọn; tí wọ́n bá dúró, àwọn àgbá náà á dúró; tí wọ́n bá sì gbéra sókè, àwọn àgbá náà á gbéra pẹ̀lú wọn, torí ẹ̀mí tó ń darí àwọn ẹ̀dá alààyè náà tún wà nínú àwọn àgbá náà.
22 Ohun kan tó tẹ́ lọ pẹrẹsẹ wà lórí àwọn ẹ̀dá alààyè náà, ó ń dán bíi yìnyín tó mọ́ kedere, ó tẹ́ pẹrẹsẹ lórí wọn.+ 23 Wọ́n na ìyẹ́ wọn sókè* lábẹ́ ohun tó tẹ́ pẹrẹsẹ náà, wọ́n sì kanra wọn. Kálukú wọn ní ìyẹ́ méjì tó fi bo ara rẹ̀ lápá kan àti méjì tó fi bo ara rẹ̀ lápá kejì. 24 Nígbà tí mo gbọ́ ìró ìyẹ́ wọn, ó dà bí ìró omi púpọ̀ tó ń rọ́ jáde, bí ìró láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè.+ Tí wọ́n bá gbéra, ìró wọn dà bíi ti àwọn ọmọ ogun. Tí wọ́n bá dúró, wọ́n á ká ìyẹ́ wọn sílẹ̀.
25 Ohùn kan dún lókè ohun tó tẹ́ pẹrẹsẹ lórí wọn. (Tí wọ́n bá sì dúró, wọ́n á ká ìyẹ́ wọn sílẹ̀.) 26 Ohun tó rí bí òkúta sàfáyà+ wà lókè ohun tó tẹ́ pẹrẹsẹ lórí wọn, ó dà bí ìtẹ́.+ Ẹnì kan tó rí bí èèyàn sì jókòó sórí ìtẹ́ náà.+ 27 Mo sì rí ohun kan tó ń dán yanran bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà,+ ó rí bí iná, ó jọ pé ó ń jó látibi ìbàdí rẹ̀ lọ sókè; mo rí ohun kan tó dà bí iná+ láti ìbàdí rẹ̀ lọ sísàlẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ sì tàn yòò yí i ká 28 bí òṣùmàrè+ tó yọ lójú ọ̀run lọ́jọ́ tí òjò rọ̀. Bí ìmọ́lẹ̀ iná tó yí i ká ṣe rí nìyẹn. Ó rí bí ògo Jèhófà.+ Nígbà tí mo rí i, mo dojú bolẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ohùn ẹnì kan tó ń sọ̀rọ̀.
2 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn,* dìde dúró kí n lè bá ọ sọ̀rọ̀.”+ 2 Nígbà tó bá mi sọ̀rọ̀, ẹ̀mí wọ inú mi, ó sì mú kí n dìde dúró+ kí n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ Ẹni tó ń bá mi sọ̀rọ̀.
3 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, màá rán ọ sí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,+ sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+ Àwọn àti àwọn baba ńlá wọn ti ṣẹ̀ mí títí di òní yìí.+ 4 Màá rán ọ sí àwọn aláìgbọràn* ọmọ àti ọlọ́kàn líle,+ kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí.’ 5 Ní tiwọn, bóyá wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, torí ọlọ̀tẹ̀ ilé+ ni wọ́n, ó dájú pé wọ́n á mọ̀ pé wòlíì kan wà láàárín wọn.+
6 “Àmọ́ ìwọ, ọmọ èèyàn, má bẹ̀rù wọn;+ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn dẹ́rù bà ọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀gún àti òṣùṣú+ yí ọ ká,* tí o sì ń gbé láàárín àwọn àkekèé. Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn dẹ́rù bà ọ́,+ má sì jẹ́ kí ojú wọn bà ọ́ lẹ́rù,+ torí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n. 7 O gbọ́dọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bóyá wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, torí ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.+
8 “Àmọ́ ìwọ, ọmọ èèyàn, gbọ́ ohun tí mò ń sọ fún ọ. Má ṣọ̀tẹ̀ bí ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí. La ẹnu rẹ, kí o sì jẹ ohun tí mo fẹ́ fún ọ.”+
9 Ni mo bá wò, mo sì rí ọwọ́ tí ẹnì kan nà sí mi,+ mo rí àkájọ ìwé tí wọ́n kọ nǹkan sí ní ọwọ́ náà.+ 10 Nígbà tó tẹ́ ẹ síwájú mi, mo rí i pé wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí i níwájú àti lẹ́yìn.+ Orin arò,* ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ àti ìpohùnréré ẹkún ló wà nínú rẹ̀.+
3 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jẹ ohun tó wà níwájú rẹ.* Jẹ àkájọ ìwé yìí, kí o sì lọ bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.”+
2 Torí náà, mo la ẹnu mi, ó sì fún mi ní àkájọ ìwé náà pé kí n jẹ ẹ́. 3 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jẹ àkájọ ìwé tí mo fún ọ yìí, kí o sì jẹ ẹ́ yó.” Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ẹ́, ó sì dùn bí oyin lẹ́nu mi.+
4 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, lọ sí ilé Ísírẹ́lì, kí o sì jíṣẹ́ mi fún wọn. 5 Torí kì í ṣe àwọn èèyàn tó ń sọ èdè tó ṣòroó lóye tàbí tí èdè wọn ṣàjèjì ni mò ń rán ọ sí, bí kò ṣe ilé Ísírẹ́lì. 6 Kì í ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń sọ èdè tó ṣòroó lóye tàbí tí èdè wọn ṣàjèjì ni mò ń rán ọ sí. Ká ní àwọn ni mo rán ọ sí ni, wọ́n á gbọ́.+ 7 Àmọ́ ilé Ísírẹ́lì ò ní tẹ́tí sí ọ torí wọn ò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.+ Olórí kunkun àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Ísírẹ́lì.+ 8 Wò ó! Mo ti mú kí ojú rẹ le bí ojú wọn, mo sì mú kí iwájú orí rẹ le bí iwájú orí wọn.+ 9 Mo ti mú kí iwájú orí rẹ dà bíi dáyámọ́ǹdì, ó le ju akọ òkúta lọ.+ Má bẹ̀rù wọn, má sì jẹ́ kí ojú wọn dẹ́rù bà ọ́,+ torí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.”
10 Ó ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ, ó ní: “Ọmọ èèyàn, fetí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fún ọ, kí o sì fi í sọ́kàn. 11 Lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ* tí wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn,+ kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀. Yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí.’”+
12 Ẹ̀mí kan wá ń gbé mi lọ,+ mo sì gbọ́ ìró ohùn kan tó ń rọ́ gììrì lẹ́yìn mi pé: “Ẹ yin Jèhófà lógo láti àyè rẹ̀.” 13 Mo sì gbọ́ ìró ìyẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà bí wọ́n ṣe ń kanra wọn+ àti ìró àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn+ àti ìró ìrọ́gìrì tó rinlẹ̀. 14 Ẹ̀mí náà gbé mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú mi lọ. Inú mi bà jẹ́, inú sì ń bí mi bí mo ṣe ń lọ, ọwọ́ Jèhófà wà lára mi lọ́nà tó lágbára. 15 Mo wá lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wà ní ìgbèkùn ní Tẹli-ábíbù, tí wọ́n ń gbé lẹ́bàá odò Kébárì,+ mo sì dúró síbi tí wọ́n ń gbé; mò ń wò suu,+ mo wà lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ méje.
16 Lẹ́yìn ọjọ́ keje, Jèhófà sọ fún mi pé:
17 “Ọmọ èèyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Ísírẹ́lì,+ nígbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, kí o bá mi kìlọ̀ fún wọn.+ 18 Tí mo bá sọ fún ẹni burúkú pé, ‘Ó dájú pé wàá kú,’ àmọ́ tí ìwọ kò kìlọ̀ fún un, tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ẹni burúkú náà pé kó jáwọ́ nínú ìwà burúkú rẹ̀ kó lè wà láàyè,+ yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ torí pé ó jẹ́ ẹni burúkú,+ àmọ́ ọwọ́ rẹ ni màá ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.*+ 19 Àmọ́ tí o bá kìlọ̀ fún ẹni burúkú tí kò sì jáwọ́ nínú iṣẹ́ ibi àti ìwà burúkú rẹ̀, yóò kú torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dájú pé ìwọ yóò gba ẹ̀mí* rẹ là.+ 20 Àmọ́ tí olódodo bá fi òdodo tó ń ṣe sílẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa,* èmi yóò fi ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú rẹ̀, yóò sì kú.+ Tí ìwọ kò bá kìlọ̀ fún un, yóò kú torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, mi ò sì ní rántí iṣẹ́ òdodo tó ti ṣe, àmọ́ ọwọ́ rẹ ni màá ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.*+ 21 Àmọ́ tí o bá ti kìlọ̀ fún olódodo náà pé kó má ṣe dẹ́ṣẹ̀, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀, ó dájú pé ó máa wà láàyè torí o ti kìlọ̀ fún un,+ ìwọ náà yóò sì gba ẹ̀mí* rẹ là.”
22 Ọwọ́ Jèhófà wá sára mi níbẹ̀, ó sì sọ fún mi pé: “Dìde, lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀.” 23 Torí náà mo dìde, mo sì lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà. Wò ó! ògo Jèhófà wà níbẹ̀,+ bí ògo tí mo rí lẹ́bàá odò Kébárì,+ mo sì dojú bolẹ̀. 24 Ẹ̀mí wá wọ inú mi, ó sì mú mi dìde dúró,+ ó bá mi sọ̀rọ̀, ó sì sọ fún mi pé:
“Lọ ti ara rẹ mọ́ inú ilé rẹ. 25 Ní ti ìwọ, ọmọ èèyàn, wọn yóò fi okùn dè ọ́, kí o má bàa kúrò láàárín wọn. 26 Màá sì mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ, o ò ní lè sọ̀rọ̀, o ò sì ní lè bá wọn wí, torí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n. 27 Àmọ́ tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, màá mú kí o sọ̀rọ̀, o sì gbọ́dọ̀ sọ fún wọn pé,+ ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí.’ Kí ẹni tó ń gbọ́ máa gbọ́,+ kí ẹni tí kò bá fẹ́ gbọ́ má sì gbọ́, nítorí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.+
4 “Ìwọ ọmọ èèyàn, gbé bíríkì kan, kí o sì gbé e síwájú rẹ. Ya àwòrán Jerúsálẹ́mù sórí rẹ̀. 2 Dó tì í,+ fi iyẹ̀pẹ̀ mọ odi yí i ká,+ mọ òkìtì láti dó tì í,+ pàgọ́ yí i ká, kí o sì gbé àwọn igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri+ yí i ká. 3 Gbé agbada onírin, kí o sì fi ṣe ògiri onírin láàárín ìwọ àti ìlú náà. Kí o wá dojú kọ ọ́, kí a sì dó tì í; ìwọ ni kí o dó tì í. Àmì ni èyí jẹ́ fún ilé Ísírẹ́lì.+
4 “Kí o wá fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ẹ̀bi ilé Ísírẹ́lì ru ara rẹ.*+ Iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀ ni wàá fi ru ẹ̀bi wọn. 5 Èmi yóò sì mú kí o fi irínwó dín mẹ́wàá (390) ọjọ́ ru ẹ̀bi ilé Ísírẹ́lì,+ èyí tó dọ́gba pẹ̀lú iye ọdún tí wọ́n fi jẹ̀bi. 6 O sì gbọ́dọ̀ lo ọjọ́ náà pé.
“Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìwọ yóò fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún dùbúlẹ̀, ìwọ yóò sì di ẹ̀bi ilé Júdà+ ru ara rẹ fún ogójì (40) ọjọ́. Ọjọ́ kan fún ọdún kan, ọjọ́ kan fún ọdún kan ni mo là kalẹ̀ fún ọ. 7 Ìwọ yóò sì yíjú sí Jerúsálẹ́mù láti dó tì í,+ láìfi aṣọ bo apá rẹ, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí rẹ̀.
8 “Wò ó! èmi yóò fi okùn dè ọ́, kí o má bàa yí ẹ̀gbẹ́ rẹ pa dà, títí ìwọ yóò fi parí ọjọ́ tí wàá fi dó tì í.
9 “Kí o sì mú àlìkámà,* ọkà bálì, ẹ̀wà pàkálà, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, jéró àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì, kí o kó wọn sínú ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe búrẹ́dì tí wàá jẹ. Iye ọjọ́ tí o fi ẹ̀gbẹ́ rẹ dùbúlẹ̀ ni wàá fi jẹ ẹ́, ìyẹn irínwó dín mẹ́wàá (390) ọjọ́.+ 10 Ìwọ yóò wọn oúnjẹ tí ó tó ogún (20) ṣékélì,* òun sì ni wàá máa jẹ lójúmọ́. Ó ní àkókò tí wàá máa jẹ ẹ́.
11 “Ṣe ni wàá máa wọn omi tí o fẹ́ mu, ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n hínì* lo máa wọ̀n. Tí àkókò bá tó ni wàá mu ún.
12 “O máa jẹ ẹ́ bí ìgbà tí ò ń jẹ búrẹ́dì ribiti tí wọ́n fi ọkà bálì ṣe; ojú wọn lo ti máa ṣe é, wàá sì fi ìgbẹ́ èèyàn dá iná rẹ̀, èyí tó ti gbẹ.” 13 Jèhófà wá sọ pé: “Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa jẹ oúnjẹ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí màá fọ́n wọn ká sí nìyẹn, oúnjẹ àìmọ́ ni wọ́n máa jẹ.”+
14 Ní mo bá sọ pé: “Rárá o, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Láti kékeré títí di báyìí, mi* ò jẹ òkú ẹran rí tàbí ẹran tí wọ́n fà ya+ tó máa sọ mí di aláìmọ́, mi ò sì jẹ ẹran kankan tó jẹ́ aláìmọ́* rí.”+
15 Ó sọ fún mi pé: “Ó dáa, màá jẹ́ kí o lo ìgbẹ́ màlúù dípò ti èèyàn, òun lo sì máa fi dá iná tí wàá fi ṣe búrẹ́dì.” 16 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, mi ò ní jẹ́ kí oúnjẹ wà* ní Jerúsálẹ́mù,+ ṣe ni wọ́n máa wọn búrẹ́dì tí wọ́n fẹ́ jẹ látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní,+ ọkàn wọn ò sì ní balẹ̀. Wọ́n máa wọn omi tí wọ́n fẹ́ mu látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n.+ 17 Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ yìí máa jẹ́ kí ẹnu yà wọ́n, bí wọ́n ṣe ń wo ara wọn, ẹ̀ṣẹ̀ wọn á sì mú kí wọ́n ṣègbé torí pé wọn ò ní búrẹ́dì àti omi tí ó tó.
5 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, mú idà kan tó mú kí o lè lò ó bí abẹ ìfárí. Fá orí rẹ àti irùngbọ̀n rẹ, kí o sì mú òṣùwọ̀n kí o lè wọn irun náà, kí o sì pín in. 2 O máa fi iná sun ìdá mẹ́ta irun náà nínú ìlú náà nígbà tí ọjọ́ tí wọ́n dó tì í bá pé.+ O máa kó ìdá mẹ́ta míì, o sì máa fi idà gé e káàkiri ìlú náà,+ kí o wá fọ́n ìdá mẹ́ta yòókù sínú afẹ́fẹ́, èmi yóò sì mú idà kí n lè lé wọn bá.+
3 “Kí o tún mú fọ́nrán díẹ̀ nínú irun náà, kí o sì wé e mọ́ aṣọ rẹ. 4 Kí o mú díẹ̀ sí i lára rẹ̀, kí o jù ú sínú iná, kí o sì sun ún di eérú. Láti ibẹ̀ ni iná yóò ti ran gbogbo ilé Ísírẹ́lì.+
5 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èyí ni Jerúsálẹ́mù. Mo ti fi í sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ìlú sì yí i ká. 6 Àmọ́, ó ti kọ àwọn ìdájọ́ àti àṣẹ mi, ìwà rẹ̀ sì burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìlú tó yí i ká lọ.+ Torí wọ́n ti kọ àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi.’
7 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí pé agídí yín pọ̀ ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká, tí ẹ kò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, tí ẹ sì kọ àwọn ìdájọ́ mi; àmọ́ ẹ tẹ̀ lé ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká,+ 8 ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò kọjú ìjà sí ọ, ìwọ ìlú,+ èmi fúnra mi yóò sì ṣèdájọ́ ní àárín rẹ lójú àwọn orílẹ̀-èdè.+ 9 Ohun tí mi ò ṣe rí ni màá ṣe fún ọ, mi ò sì tún ní ṣe irú rẹ̀ mọ́, torí gbogbo ohun ìríra tí ò ń ṣe.+
10 “‘“Ṣe ni àwọn bàbá tó wà ní àárín yín yóò jẹ àwọn ọmọ wọn,+ àwọn ọmọ yóò sì jẹ àwọn bàbá wọn, màá ṣe ìdájọ́ yín, màá sì fọ́n àwọn tó ṣẹ́ kù nínú yín káàkiri.”’*+
11 “‘Torí náà, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘torí pé ẹ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín àti àwọn ohun ìríra tí ẹ̀ ń ṣe sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ èmi náà yóò kọ̀ yín;* mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín.+ 12 Àjàkálẹ̀ àrùn* tàbí ìyàn máa pa ìdá mẹ́ta lára yín. Wọ́n á sì fi idà pa ìdá mẹ́ta míì láyìíká yín.+ Màá fọ́n ìdá mẹ́ta yòókù káàkiri,* màá sì fa idà yọ láti fi lé wọn.+ 13 Mi ò sì ní bínú mọ́, inú mi ò ní ru sí wọn mọ́, màá ti tẹ́ ara mi lọ́rùn.+ Nígbà tí mo bá ti bínú gidigidi sí wọn tán, wọ́n á mọ̀ pé èmi, Jèhófà, ti sọ pé èmi nìkan ni mo fẹ́ kí ẹ máa jọ́sìn.+
14 “‘Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro, màá sì mú kí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká àti àwọn tó ń kọjá lọ máa gàn ọ́.+ 15 Wọ́n á gàn ọ́, wọ́n á sì fi ọ́ ṣẹlẹ́yà.+ Wọ́n á kọ́gbọ́n lára rẹ, ẹ̀rù á sì ba àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, nígbà tí mo bá fi ìbínú àti ìrunú dá ọ lẹ́jọ́ tí mo sì fìyà jẹ ọ́ gidigidi. Èmi, Jèhófà, ti sọ ọ́.
16 “‘Màá fi ìyàn kọ lù wọ́n, ó máa pa wọ́n run bí ìgbà tí mo bá ta wọ́n ní ọfà olóró. Ọfà tí mo bá ta yóò run yín.+ Màá mú kí ìyàn náà le sí i torí pé màá dáwọ́ oúnjẹ yín dúró.*+ 17 Màá fi ìyàn kọ lù yín, màá rán àwọn ẹranko burúkú sí yín,+ wọ́n á sì pa yín lọ́mọ jẹ. Àjàkálẹ̀ àrùn máa bò yín, ìtàjẹ̀sílẹ̀ á kún ilẹ̀ yín, màá sì fi idà kọ lù yín.+ Èmi, Jèhófà, ti sọ ọ́.’”
6 Jèhófà tún sọ fún mi pé: 2 “Ọmọ èèyàn, yíjú sí àwọn òkè Ísírẹ́lì, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí wọn. 3 Kí o sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ: Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké, fún àwọn odò àti àwọn àfonífojì nìyí: “Wò ó! Èmi yóò fi idà bá yín jà, èmi yóò sì run àwọn ibi gíga yín. 4 Màá wó àwọn pẹpẹ yín, màá fọ́ àwọn ohun tí ẹ fi ń sun tùràrí,+ màá sì ju òkú àwọn èèyàn yín síwájú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín.*+ 5 Èmi yóò ju òkú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì síwájú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn, èmi yóò sì fọ́n egungun yín ká sí àyíká àwọn pẹpẹ yín.+ 6 Ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé, àwọn ìlú yóò di ahoro,+ wọ́n á wó àwọn ibi gíga, yóò sì di ahoro.+ Wọ́n á wó àwọn pẹpẹ yín, wọ́n á sì tú u ká, àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín máa pa run, wọ́n á wó àwọn ohun tí ẹ fi ń sun tùràrí, iṣẹ́ yín á sì pa rẹ́. 7 Òkú á sùn lọ bẹẹrẹbẹ láàárín yín,+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+
8 “‘“Àmọ́ màá mú kí àwọn kan ṣẹ́ kù, torí àwọn kan lára yín á bọ́ lọ́wọ́ idà àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí ẹ bá fọ́n ká sí àwọn ilẹ̀.+ 9 Àwọn tó bá yè bọ́ yóò rántí mi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó kó wọn lẹ́rú.+ Wọ́n á rí i pé ó dùn mí gan-an bí ọkàn àìṣòótọ́* wọn ṣe mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí mi+ àti bí ojú wọn ṣe mú kí ọkàn wọn fà sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.*+ Gbogbo iṣẹ́ ibi àtàwọn ohun ìríra tí wọ́n ti ṣe yóò kó ìtìjú bá wọn, wọ́n á sì kórìíra rẹ̀ gidigidi.+ 10 Wọ́n á sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà àti pé àjálù yìí tí mo sọ pé màá mú bá wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán.”’+
11 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Pàtẹ́wọ́, kí o fẹsẹ̀ kilẹ̀, kí o sì kẹ́dùn torí gbogbo ìwà ibi àti ohun tó ń ríni lára tí ilé Ísírẹ́lì ṣe, torí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò pa wọ́n.+ 12 Àjàkálẹ̀ àrùn yóò pa ẹni tó wà lọ́nà jíjìn, idà yóò pa ẹni tó wà nítòsí, ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ́ kù, tó sì bọ́ lọ́wọ́ ìwọ̀nyí ni ìyàn yóò pa; bí mo ṣe máa bínú sí wọn gidigidi nìyẹn.+ 13 Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ nígbà tí òkú wọn bá sùn lọ bẹẹrẹbẹ níbi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn, tí àwọn òkú náà yí àwọn pẹpẹ wọn ká,+ lórí gbogbo òkè kékeré àti òkè gíga, lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ àti lábẹ́ àwọn ẹ̀ka igi ńláńlá tí wọ́n ti rú àwọn ẹbọ olóòórùn dídùn* láti fi wá ojúure gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin wọn.+ 14 Èmi yóò na ọwọ́ mi kí n lè fìyà jẹ wọ́n, màá sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro, ibi tí wọ́n ń gbé máa di ahoro ju aginjù tó wà nítòsí Díbílà lọ. Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”
7 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìyí: ‘Òpin! Òpin ti dé bá igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà. 3 Òpin ti dé bá yín báyìí, màá bínú sí yín. Màá fi iṣẹ́ ọwọ́ yín dá yín lẹ́jọ́, màá sì pè yín wá jíhìn torí gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe. 4 Mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín,+ torí màá fi ìwà yín san yín lẹ́san. Ẹ ó jìyà gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe.+ Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’+
5 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Wò ó! Àjálù, àjálù kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ń bọ̀.+ 6 Òpin ń bọ̀; òpin yóò dé; yóò dé* bá yín lójijì. Wò ó! Ó ń bọ̀. 7 Ó* ti dé bá yín, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ náà. Àkókò ń bọ̀, ọjọ́ náà sún mọ́lé.+ Gbogbo nǹkan dà rú, ariwo ayọ̀ kò sì dún lórí àwọn òkè.
8 “‘Láìpẹ́, inú mi á ru sí yín,+ màá bínú sí yín gidigidi.+ Màá fi iṣẹ́ ọwọ́ yín dá yín lẹ́jọ́, màá sì pè yín wá jíhìn torí gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe. 9 Mi ò ní ṣàánú yín; mi ò sì ní yọ́nú sí yín.+ Màá fi ìwà yín san yín lẹ́san, ẹ ó sì jìyà gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe. Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń fìyà jẹ yín.+
10 “‘Wò ó, ọjọ́ náà! Wò ó, ó ń bọ̀!+ Ó* ti dé bá yín; ọ̀pá ti yọ ìtànná, ìgbéraga* sì ti rúwé. 11 Ìwà ipá ti hù, ó sì ti di ọ̀pá ìwà burúkú.+ Wọn ò ní yè bọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ọrọ̀ wọn, àwọn èèyàn àti òkìkí wọn kò sì ní yè bọ́. 12 Àkókò á tó, ọjọ́ náà á dé. Kí ẹni tó ń ra nǹkan má ṣe yọ̀, kí ẹni tó sì ń ta nǹkan má ṣe ṣọ̀fọ̀, torí pé mo bínú sí gbogbo wọn.*+ 13 Tí ẹni tó ta nǹkan bá tiẹ̀ yè é, kò ní pa dà sí ìdí ohun tó tà, torí ìran náà kan gbogbo wọn. Kò sẹ́ni tó máa pa dà, kò sì sẹ́ni tó máa gba ara rẹ̀ là torí àṣìṣe òun fúnra rẹ̀.*
14 “‘Wọ́n ti fun kàkàkí,+ gbogbo èèyàn sì ti gbára dì, àmọ́ kò sẹ́ni tó ń lọ sí ojú ogun, torí pé mo bínú sí gbogbo wọn.+ 15 Idà wà níta,+ àjàkálẹ̀ àrùn àti ìyàn sì wà nínú. Idà ni yóò pa ẹnikẹ́ni tó bá wà ní pápá, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa run àwọn tó bá wà nínú ìlú.+ 16 Àwọn tó bá jàjà bọ́ yóò sá lọ sórí àwọn òkè, kálukú wọn á sì ké tẹ̀dùntẹ̀dùn torí àṣìṣe rẹ̀ bí àwọn àdàbà inú àfonífojì.+ 17 Gbogbo ọwọ́ wọn á rọ jọwọrọ, omi á sì máa ro tótó ní orúnkún wọn.*+ 18 Wọ́n ti wọ aṣọ ọ̀fọ̀,*+ jìnnìjìnnì sì bá wọn.* Ojú á ti gbogbo wọn, orí gbogbo wọn á sì pá.*+
19 “‘Wọ́n á ju fàdákà wọn sí ojú ọ̀nà, wúrà wọn á sì di ohun ìríra lójú wọn. Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.+ Kò ní tẹ́ wọn* lọ́rùn, wọn ò sì ní yó, torí ó* ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ tó ń mú kí wọ́n ṣe àṣìṣe. 20 Wọ́n ń fi ẹwà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wọn yangàn, wọ́n sì fi wọ́n* ṣe àwọn ère wọn tó ń ríni lára, àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.+ Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kó di ohun ìríra lójú wọn. 21 Màá mú kí àwọn àjèjì kó wọn, màá sì mú kí àwọn ẹni burúkú inú ayé kó wọn* bí ẹrù ogun, wọ́n á sì sọ ọ́ di aláìmọ́.
22 “‘Èmi yóò yí ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọ́n á sì sọ ibi ìṣúra* mi di aláìmọ́, àwọn olè á wọ ibẹ̀, wọ́n á sì sọ ọ́ di aláìmọ́.+
23 “‘Ṣe ẹ̀wọ̀n,*+ torí wọ́n ń fi ìdájọ́ ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà,+ ìwà ipá sì kún ìlú náà.+ 24 Màá mú orílẹ̀-èdè tó burú jù wá,+ wọ́n á sì gba àwọn ilé wọn,+ màá fòpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, àwọn ibi mímọ́ wọn á sì di aláìmọ́.+ 25 Nígbà tí wọ́n bá ń jẹ̀rora, wọ́n á wá àlàáfíà àmọ́ wọn kò ní rí i.+ 26 Àjálù á ré lu àjálù, wọ́n á gbọ́ ìròyìn kan tẹ̀ lé òmíràn, àwọn èèyàn á wá ìran lọ sọ́dọ̀ wòlíì,+ àmọ́ òfin* yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àlùfáà, ìmọ̀ràn ò sì ní sí lẹ́nu àwọn àgbààgbà.+ 27 Ọba yóò ṣọ̀fọ̀,+ ìbànújẹ́* máa bá àwọn ìjòyè, ìbẹ̀rù yóò sì mú kí ọwọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa gbọ̀n. Ìwà wọn ni màá fi san wọ́n lẹ́san, èmi yóò sì dá wọn lẹ́jọ́ bí wọ́n ṣe dá àwọn míì lẹ́jọ́. Wọ́n á sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”+
8 Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹfà, ọdún kẹfà, nígbà tí mo jókòó sínú ilé mi, tí àwọn àgbààgbà Júdà sì jókòó síwájú mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fún mi lágbára níbẹ̀. 2 Bí mo ṣe ń wò, mo rí ẹnì kan tó rí bí iná; ó jọ pé iná wà níbi ìbàdí rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀.+ Láti ìbàdí rẹ̀ lọ sókè, ó mọ́lẹ̀, ó rí bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà tó ń dán yanran.+ 3 Ó wá na ohun tó dà bí ọwọ́ jáde, ó fa irun orí mi, ẹ̀mí kan sì gbé mi nínú ìran látọ̀dọ̀ Ọlọ́run lọ sí agbedeméjì ayé àti ọ̀run. Ó gbé mi wá sí Jerúsálẹ́mù, sí ẹnubodè inú,+ èyí tó kọjú sí àríwá, níbi tí ère* owú tó ń múni jowú wà.+ 4 Wò ó! ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì wà níbẹ̀,+ ó dà bí ohun tí mo rí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀.+
5 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jọ̀ọ́ gbójú sókè kí o wo àríwá.” Torí náà, mo wo àríwá, mo sì rí ère* owú náà ní àríwá ẹnubodè pẹpẹ. 6 Ó sì sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé o rí ohun ìríra tó burú jáì tí ilé Ísírẹ́lì ń ṣe níbí,+ tó mú kí n jìnnà sí ibi mímọ́ mi?+ O máa rí àwọn ohun tó ń ríni lára tó tún burú ju èyí lọ.”
7 Ó wá mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá, nígbà tí mo sì wo ibẹ̀, mo rí ihò kan lára ògiri. 8 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jọ̀ọ́ dá ògiri náà lu.” Ni mo bá dá ògiri náà lu, mo sì rí ẹnu ọ̀nà kan. 9 Ó sọ fún mi pé: “Wọlé, kí o lè rí iṣẹ́ ibi tó ń ríni lára tí wọ́n ń ṣe níbí.” 10 Torí náà, mo wọlé, mo wò ó, mo sì rí oríṣiríṣi àwòrán ohun tó ń rákò àti ẹranko tó ń kóni nírìíra+ àti gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin* ilé Ísírẹ́lì;+ wọ́n gbẹ́ ẹ sí ara ògiri káàkiri. 11 Àádọ́rin (70) ọkùnrin lára àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì dúró níwájú wọn, Jasanáyà ọmọ Ṣáfánì+ sì wà lára wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú àwo tùràrí rẹ̀ dání, èéfín tùràrí tó ní òórùn dídùn sì ń gòkè lọ.+ 12 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn, kálukú nínú yàrá inú tó kó* àwọn ère rẹ̀ sí? Wọ́n ń sọ pé, ‘Jèhófà ò rí wa. Jèhófà ti fi ilẹ̀ wa sílẹ̀.’”+
13 Ó wá sọ fún mi pé: “Wàá rí àwọn ohun tó ń ríni lára tí wọ́n ń ṣe tó tún burú ju èyí lọ.” 14 Torí náà, ó mú mi wá sí ẹnubodè àríwá ní ilé Jèhófà, mo sì rí àwọn obìnrin tí wọ́n jókòó síbẹ̀, tí wọ́n ń sunkún torí ọlọ́run tí wọ́n ń pè ní Támúsì.
15 Ó sọ fún mi síwájú sí i pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé ìwọ náà rí i? Wàá rí àwọn ohun ìríra tó tún burú ju èyí lọ.”+ 16 Torí náà, ó mú mi wá sí àgbàlá inú ní ilé Jèhófà.+ Ní ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì Jèhófà, láàárín ibi àbáwọlé* àti pẹpẹ, nǹkan bí ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) wà níbẹ̀ tí wọ́n kẹ̀yìn sí tẹ́ńpìlì Jèhófà, tí wọ́n sì kọjú sí ìlà oòrùn; wọ́n ń forí balẹ̀ fún oòrùn níbẹ̀.+
17 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé ìwọ náà rí i? Ṣé ohun tí kò tó nǹkan ni lójú ilé Júdà láti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, tí wọ́n ń hu ìwà ipá ní gbogbo ilẹ̀ náà,+ tí wọ́n sì ń ṣẹ̀ mí? Wọ́n ń na ẹ̀ka* sí mi ní imú. 18 Torí náà, màá bínú sí wọn. Mi ò ní ṣàánú wọn, mi ò sì ní yọ́nú sí wọn.+ Bí wọ́n bá tiẹ̀ kígbe tantan kí n lè gbọ́, mi ò ní dá wọn lóhùn.”+
9 Lẹ́yìn náà, ó fi ohùn tó dún ketekete bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Pe àwọn tí yóò fìyà jẹ ìlú náà wá, kí kálukú wọn mú ohun ìjà tó máa fi pa á run dání!”
2 Mo rí ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n ń bọ̀ láti ẹnubodè apá òkè,+ tó dojú kọ àríwá, kálukú mú ohun ìjà tí wọ́n fi ń fọ́ nǹkan dání; ọkùnrin kan wà lára wọn tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,* ìwo yíǹkì akọ̀wé* sì wà ní ìbàdí rẹ̀. Wọ́n wọlé, wọ́n sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ bàbà.+
3 Ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ wá gbéra lórí àwọn kérúbù níbi tó wà tẹ́lẹ̀, lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé náà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pe ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, tí ìwo yíǹkì akọ̀wé wà ní ìbàdí rẹ̀. 4 Jèhófà sọ fún un pé: “Lọ káàkiri ìlú náà, káàkiri Jerúsálẹ́mù, kí o sì sàmì sí iwájú orí àwọn èèyàn tó ń kẹ́dùn, tí wọ́n sì ń kérora+ torí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe ní ìlú náà.”+
5 Mo sì gbọ́ tó sọ fún àwọn yòókù pé: “Ẹ tẹ̀ lé e káàkiri ìlú náà, kí ẹ sì pa wọ́n. Ẹ má ṣàánú wọn, ẹ má sì yọ́nú sí wọn rárá.+ 6 Ẹ pa àwọn àgbàlagbà ọkùnrin pátápátá àti àwọn géńdé ọkùnrin, wúńdíá, ọmọdé àti àwọn obìnrin.+ Àmọ́ ẹ má ṣe sún mọ́ ẹnikẹ́ni tí àmì náà wà lórí rẹ̀.+ Ibi mímọ́ mi ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀.”+ Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà níwájú ilé náà.+ 7 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ ilé náà di ẹlẹ́gbin, kí ẹ sì fi òkú èèyàn kún inú àwọn àgbàlá.+ Ẹ lọ!” Ni wọ́n bá lọ, wọ́n sì pa àwọn èèyàn ní ìlú náà.
8 Bí wọ́n ṣe ń pa wọ́n, ó wá ku èmi nìkan, mo bá dojú bolẹ̀, mo sì ké jáde pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ṣé inú tó ń bí ọ sí Jerúsálẹ́mù máa mú kí o pa gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì run ni?”+
9 Torí náà, ó sọ fún mi pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì àti Júdà pọ̀ gidigidi.+ Ìtàjẹ̀sílẹ̀ kún ilẹ̀ náà,+ ìwà ìbàjẹ́ sì kún ìlú náà.+ Wọ́n ń sọ pé, ‘Jèhófà ti fi ilẹ̀ wa sílẹ̀, Jèhófà ò sì rí wa.’+ 10 Àmọ́ ní tèmi, mi ò ní ṣàánú wọn, mi ò sì ní yọ́nú sí wọn.+ Màá fi ìwà wọn san wọ́n lẹ́san.”
11 Mo wá rí ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, tí ìwo yíǹkì wà ní ìbàdí rẹ̀, ó pa dà wá jíṣẹ́ pé: “Mo ti ṣe ohun tí o pa láṣẹ fún mi.”
10 Bí mo ṣe ń wò, mo rí ohun tó rí bí òkúta sàfáyà lókè ohun tó tẹ́ pẹrẹsẹ lórí àwọn kérúbù náà, ó sì dà bí ìtẹ́.+ 2 Ó wá sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀*+ náà pé: “Wọ àárín àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà,+ lábẹ́ àwọn kérúbù, kó ẹyin iná tó ń jó + láàárín àwọn kérúbù náà sí ọwọ́ rẹ méjèèjì, kí o sì fọ́n ọn ká sórí ìlú náà.”+ Mo wá rí i tó wọlé.
3 Àwọn kérúbù náà dúró ní apá ọ̀tún ilé náà nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùukùu* sì kún àgbàlá inú. 4 Ògo Jèhófà+ gbéra láti orí àwọn kérúbù wá sí ẹnu ọ̀nà ilé náà, ìkùukùu sì bẹ̀rẹ̀ sí í kún inú ilé náà díẹ̀díẹ̀,+ ògo Jèhófà sì mọ́lẹ̀ yòò ní gbogbo àgbàlá náà. 5 Ìró ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà sì dé àgbàlá ìta, ó dún bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmarè bá ń sọ̀rọ̀.+
6 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ pé: “Mú iná láàárín àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà, láàárín àwọn kérúbù,” ó sì wọlé, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbá kẹ̀kẹ́ náà. 7 Ọ̀kan lára àwọn kérúbù náà wá na ọwọ́ rẹ̀ jáde síbi iná tó wà láàárín wọn.+ Ó mú díẹ̀ lára rẹ̀, ó sì kó o sí ọwọ́ méjèèjì ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀.+ Ọkùnrin náà gbà á, ó sì jáde lọ. 8 Àwọn kérúbù náà ní ohun tó dà bí ọwọ́ èèyàn lábẹ́ ìyẹ́ wọn.+
9 Bí mo ṣe ń wò, mo rí àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rin lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù náà, àgbá kẹ̀kẹ́ kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan, àwọn àgbá náà ń dán bí òkúta kírísóláítì.+ 10 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jọra, wọ́n rí bí ìgbà tí àgbá kẹ̀kẹ́ kan wà nínú àgbá kẹ̀kẹ́ míì. 11 Tí wọ́n bá ń lọ, wọ́n lè lọ sí ibikíbi ní ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin láìṣẹ́rí pa dà, torí ibi tí orí bá kọjú sí ni wọ́n máa ń lọ láìṣẹ́rí pa dà. 12 Gbogbo ara wọn, ẹ̀yìn wọn, ọwọ́ wọn, ìyẹ́ apá wọn àti àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà, àgbá kẹ̀kẹ́ àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ní ojú káàkiri ara wọn.+ 13 Ní ti àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà, mo gbọ́ ohùn kan tó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbéra, ẹ̀yin àgbá kẹ̀kẹ́!”
14 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn* ní ojú mẹ́rin. Ojú àkọ́kọ́ jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ojú èèyàn, ojú kẹta jẹ́ ojú kìnnìún, ojú kẹrin sì jẹ́ ojú idì.+
15 Àwọn kérúbù náà á sì dìde, àwọn ni ẹ̀dá alààyè* tí mo rí ní odò Kébárì,+ 16 tí àwọn kérúbù náà bá sì gbéra, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà á gbéra pẹ̀lú wọn; tí wọ́n bá sì na ìyẹ́ apá wọn kí wọ́n lè lọ sókè, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà kì í yí tàbí kí wọ́n kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.+ 17 Tí wọ́n bá dúró, àwọn àgbá náà á dúró; tí wọ́n bá sì gbéra, àwọn àgbá náà á gbéra pẹ̀lú wọn, torí ẹ̀mí tó ń darí àwọn ẹ̀dá alààyè náà* wà nínú àwọn àgbá náà.
18 Ògo Jèhófà+ wá kúrò ní ẹnu ọ̀nà ilé náà, ó sì dúró lórí àwọn kérúbù náà.+ 19 Bí mo ṣe ń wò, àwọn kérúbù náà wá na ìyẹ́ apá wọn, wọ́n sì gbéra nílẹ̀. Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n gbéra. Wọ́n dúró ní ẹnubodè ìlà oòrùn ní ilé Jèhófà, ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lórí wọn.+
20 Àwọn ni ẹ̀dá alààyè* tí mo rí lábẹ́ ìtẹ́ Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní odò Kébárì,+ mo wá mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n. 21 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú mẹ́rin, ìyẹ́ apá mẹ́rin, ohun tó sì dà bí ọwọ́ èèyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ apá wọn.+ 22 Ojú wọn sì dà bí àwọn ojú tí mo rí lẹ́bàá odò Kébárì.+ Iwájú tààrà ni kálukú wọn ń lọ.+
11 Ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì gbé mi wá sí ẹnubodè ìlà oòrùn ilé Jèhófà, ìyẹn ẹnubodè tó dojú kọ ìlà oòrùn.+ Mo rí ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) níbi àbáwọ ẹnubodè náà, Jasanáyà ọmọ Ásúrì àti Pẹlatáyà ọmọ Bẹnáyà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn èèyàn náà sì wà lára wọn.+ 2 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń gbèrò ibi, tí wọ́n sì ń gbani nímọ̀ràn ìkà ní* ìlú yìí. 3 Wọ́n ń sọ pé, ‘Ṣebí àkókò yìí ló yẹ ká kọ́ ilé?+ Ìlú náà* ni ìkòkò oúnjẹ,*+ àwa sì ni ẹran.’
4 “Torí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí wọn. Sọ tẹ́lẹ̀, ọmọ èèyàn.”+
5 Ẹ̀mí Jèhófà wá bà lé mi,+ ó sì sọ fún mi pé: “Sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Òótọ́ lẹ sọ, ilé Ísírẹ́lì, mo sì mọ ohun tí ẹ̀ ń rò.* 6 Ẹ ti fa ikú ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìlú yìí, ẹ sì ti fi òkú àwọn èèyàn kún ojú ọ̀nà rẹ̀.”’”+ 7 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Òkú àwọn èèyàn tí ẹ fọ́n ká sí ìlú náà ni ẹran, ìlú náà sì ni ìkòkò oúnjẹ.+ Àmọ́ wọ́n máa mú ẹ̀yin alára kúrò níbẹ̀.’”
8 “‘Ẹ̀ ń bẹ̀rù idà,+ òun ni màá sì fi bá yín jà,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 9 ‘Èmi yóò mú yín jáde kúrò nínú rẹ̀, màá mú kí ọwọ́ àwọn àjèjì tẹ̀ yín, màá sì dá yín lẹ́jọ́.+ 10 Idà ni yóò pa yín.+ Èmi yóò dá yín lẹ́jọ́ ní ààlà Ísírẹ́lì,+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+ 11 Ìlú náà kò ní jẹ́ ìkòkò oúnjẹ fún yín, ẹ̀yin kọ́ lẹ sì máa di ẹran inú rẹ̀; èmi yóò dá yín lẹ́jọ́ ní ààlà Ísírẹ́lì, 12 ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà. Torí ẹ kò rìn nínú àwọn ìlànà mi, ẹ kò sì tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi,+ àmọ́ ẹ tẹ̀ lé ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.’”+
13 Bí mo ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà tán, Pẹlatáyà ọmọ Bẹnáyà kú. Ni mo bá dojú bolẹ̀, mo sì ké jáde pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ṣé o máa pa àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì run ni?”+
14 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 15 “Ọmọ èèyàn, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ti sọ fún àwọn arákùnrin rẹ tó ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ má ṣe sún mọ́ Jèhófà rárá. Àwa la ni ilẹ̀ náà; wọ́n ti fún wa bí ohun ìní.’ 16 Torí náà, sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mú kí wọ́n lọ sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀ náà,+ èmi yóò di ibi mímọ́ fún wọn fúngbà díẹ̀, ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n lọ.”’+
17 “Torí náà, sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú yín kúrò láàárín àwọn èèyàn, màá kó yín jọ láti àwọn ilẹ̀ tí mo fọ́n yín ká sí, màá sì fún yín ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.+ 18 Wọ́n á pa dà síbẹ̀, wọ́n á sì mú gbogbo ohun ìríra àti gbogbo iṣẹ́ tó ń ríni lára kúrò nínú rẹ̀.+ 19 Èmi yóò mú kí ọkàn wọn ṣọ̀kan,*+ màá sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn;+ màá mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn,+ màá sì fún wọn ní ọkàn ẹran,*+ 20 kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìdájọ́ mi, kí wọ́n sì máa rìn nínú rẹ̀. Wọ́n á wá di èèyàn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn.”’
21 “‘“Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ọkàn wọn ṣì ń fà sí àwọn ohun tó ń ríni lára tó sì ń kóni nírìíra tí wọ́n ń ṣe, màá fi ìwà wọn san wọ́n lẹ́san,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’”
22 Àwọn kérúbù náà wá na ìyẹ́ apá wọn, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn,+ ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lórí wọn.+ 23 Ògo Jèhófà + wá gbéra kúrò ní ìlú náà, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà oòrùn ìlú náà.+ 24 Ẹ̀mí wá gbé mi sókè nínú ìran tí ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí n rí, ó gbé mi wá sọ́dọ̀ àwọn tó wà ní ìgbèkùn ní Kálídíà. Bí mi ò ṣe rí ìran tí mo rí mọ́ nìyẹn. 25 Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ gbogbo ohun tí Jèhófà fi hàn mí fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn.
12 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, àárín ọlọ̀tẹ̀ ilé lò ń gbé. Wọ́n ní ojú láti rí, àmọ́ wọn ò ríran, wọ́n ní etí láti gbọ́, àmọ́ wọn ò gbọ́ràn,+ torí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.+ 3 Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, di ẹrù tí wàá gbé lọ sí ìgbèkùn. Kí o wá lọ sí ìgbèkùn ní ojúmọmọ níṣojú wọn. Lọ sí ìgbèkùn láti ilé rẹ sí ibòmíì níṣojú wọn. Bóyá wọ́n á kíyè sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n. 4 Gbé ẹrù tí o fẹ́ kó lọ sí ìgbèkùn jáde ní ojúmọmọ níṣojú wọn, tó bá sì di ìrọ̀lẹ́, kí o kúrò nílé níṣojú wọn bí ẹni tí wọ́n ń mú lọ sí ìgbèkùn.+
5 “Dá ògiri lu níṣojú wọn, kí o sì gbé ẹrù rẹ gba inú ihò náà.+ 6 Gbé ẹrù rẹ lé èjìká níṣojú wọn, kí o sì gbé e jáde nínú òkùnkùn. Bo ojú rẹ kí o má bàa rí ilẹ̀, torí èmi yóò fi ọ́ ṣe àmì fún ilé Ísírẹ́lì.”+
7 Mo ṣe ohun tó pa láṣẹ fún mi. Ní ojúmọmọ, mo gbé ẹrù mi jáde bí ẹrù ẹni tó ń lọ sí ìgbèkùn, mo sì fi ọwọ́ dá ògiri náà lu ní ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí ilẹ̀ sì ṣú, ìṣojú wọn gan-an ni mo ṣe gbé ẹrù mi jáde lórí èjìká mi.
8 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 9 “Ọmọ èèyàn, ṣebí ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé bi ọ́ pé, ‘Kí lò ń ṣe?’ 10 Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ọ̀rọ̀ yìí kan ìjòyè+ Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tó wà nínú ìlú náà.”’
11 “Sọ pé, ‘Àmì ni mo jẹ́ fún yín.+ Ohun tí mo ṣe ni wọ́n á ṣe sí wọn. Wọn yóò lọ sí ìgbèkùn, wọ́n á kó wọn lẹ́rú.+ 12 Ìjòyè àárín wọn yóò gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká, yóò sì lọ nínú òkùnkùn. Ó máa dá ògiri lu, yóò sì gbé ẹrù rẹ̀ gba inú ihò náà.+ Ó máa bo ojú rẹ̀ kó má bàa rí ilẹ̀.’ 13 Èmi yóò ju àwọ̀n mi sí i láti fi mú un.+ Màá wá mú un lọ sí Bábílónì, sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, àmọ́ kò ní rí i; ibẹ̀ ló sì máa kú sí.+ 14 Gbogbo àwọn tó yí i ká, àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni màá fọ́n káàkiri;+ èmi yóò sì fa idà yọ kí n lè lé wọn bá.+ 15 Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá fọ́n wọn káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì tú wọn ká sí àwọn ilẹ̀ náà. 16 Àmọ́ màá gba díẹ̀ lára wọn lọ́wọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun tó ń ríni lára tí wọ́n ṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn yóò lọ; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”
17 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 18 “Ọmọ èèyàn, máa gbọ̀n rìrì bí o ṣe ń jẹ oúnjẹ rẹ, kí ẹ̀rù máa bà ọ́, kí ọkàn rẹ má sì balẹ̀ bí o ṣe ń mu omi rẹ.+ 19 Sọ fún àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìyí: “Ọkàn wọn ò ní balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń jẹ oúnjẹ wọn, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n bí wọ́n ṣe ń mu omi wọn, torí ilẹ̀ wọn á di ahoro pátápátá+ torí ìwà ipá gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀.+ 20 Àwọn ìlú tí wọ́n ń gbé yóò di ahoro, ilẹ̀ náà yóò sì ṣófo;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”+
21 Jèhófà tún sọ fún mi pé: 22 “Ọmọ èèyàn, òwe wo ni wọ́n ń pa ní Ísírẹ́lì yìí, pé, ‘Ọjọ́ ń lọ, gbogbo ìran ò ṣẹ’?+ 23 Torí náà, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Mi ò ní jẹ́ kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí mọ́ ní Ísírẹ́lì, wọn ò sì ní pa á lówe mọ́.”’ Àmọ́ sọ fún wọn pé, ‘Ọjọ́ ń sún mọ́lé,+ gbogbo ìran yóò sì ṣẹ.’ 24 Torí kò ní sí ìran èké tàbí ìwoṣẹ́ ẹ̀tàn mọ́ nínú ilé Ísírẹ́lì.+ 25 ‘“Torí èmi Jèhófà, yóò sọ̀rọ̀. Ohun tí mo bá sọ sì máa ṣẹ láìjáfara.+ Ìwọ ọlọ̀tẹ̀ ilé, ní àwọn ọjọ́ rẹ,+ ni èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ náà, màá sì mú un ṣẹ,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’”
26 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 27 “Ọmọ èèyàn, ohun tí àwọn èèyàn* Ísírẹ́lì ń sọ nìyí, ‘Ìran tó ń rí ṣì máa pẹ́ kó tó ṣẹ, ó sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú tó ṣì jìnnà gan-an.’+ 28 Torí náà, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “‘Kò sí èyí tó máa falẹ̀ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ mi; gbogbo ohun tí mo bá sọ ló máa ṣẹ,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’”
13 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí àwọn wòlíì Ísírẹ́lì,+ kí o sì sọ fún àwọn tó ń hùmọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tiwọn* pé,+ ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. 3 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ gbé, ẹ̀yin òmùgọ̀ wòlíì, tí ẹ̀ ń sọ èrò ọkàn yín, láìrí nǹkan kan!+ 4 Ìwọ Ísírẹ́lì, àwọn wòlíì rẹ dà bíi kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàárín àwọn àwókù ilé. 5 Ẹ ò ní lọ sí àwọn ibi tó ti fọ́ lára àwọn ògiri olókùúta láti tún un kọ́ fún ilé Ísírẹ́lì,+ kí Ísírẹ́lì má bàa ṣubú lójú ogun ní ọjọ́ Jèhófà.”+ 6 “Ìran èké ni wọ́n rí, àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ni wọ́n sì sọ, àwọn tó ń sọ pé, ‘Ọ̀rọ̀ Jèhófà ni pé,’ tó sì jẹ́ pé Jèhófà ò rán wọn, wọ́n sì ti dúró kí ọ̀rọ̀ wọn lè ṣẹ.+ 7 Ṣebí ìran èké lẹ rí, àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ lẹ sì sọ nígbà tí ẹ sọ pé, ‘Ọ̀rọ̀ Jèhófà ni pé,’ tó sì jẹ́ pé mi ò sọ nǹkan kan?”’
8 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “‘Torí ẹ ti parọ́ tí ẹ sì ń rí ìran èké, mo kẹ̀yìn sí yín,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”+ 9 Àwọn wòlíì tó ń rí ìran èké àti àwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ máa jìyà lọ́wọ́ mi.+ Wọn ò ní sí lára àwọn èèyàn tí mo fọkàn tán; orúkọ wọn ò ní sí nínú àkọsílẹ̀ orúkọ ilé Ísírẹ́lì; wọn ò ní pa dà sórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+ 10 Gbogbo èyí jẹ́ torí pé wọ́n ti ṣi àwọn èèyàn mi lọ́nà, bí wọ́n ṣe ń sọ pé, “Àlàáfíà wà!” nígbà tí kò sí àlàáfíà.+ Tí wọ́n bá mọ ògiri tí kò lágbára, wọ́n á kùn ún ní ẹfun.’*+
11 “Sọ fún àwọn tó ń kun ògiri ní ẹfun pé, ó máa wó. Àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò yóò rọ̀, yìnyín* máa já bọ́, ìjì líle yóò sì wó o palẹ̀.+ 12 Tí ògiri náà bá sì wó, wọ́n á bi yín pé, ‘Ẹfun tí ẹ fi kùn ún dà?’+
13 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Màá fi ìbínú mú kí ìjì líle jà, màá fi ìrunú rọ àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò, ìbínú tó le ni màá sì fi rọ yìnyín láti pa á run. 14 Èmi yóò wó ògiri tí ẹ kùn ní ẹfun, màá ya á lulẹ̀, ìpìlẹ̀ rẹ̀ á sì hàn síta. Tí ìlú náà bá pa run, ẹ máa kú sínú rẹ̀; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
15 “‘Tí mo bá ti bínú tán sí ògiri náà àti àwọn tó kùn ún ní ẹfun, èmi yóò sọ fún yín pé: “Ògiri náà kò sí mọ́, àwọn tó sì ń kùn ún ní ẹfun kò sí mọ́.+ 16 Kò sí wòlíì mọ́ ní Ísírẹ́lì, àwọn tó ń sọ tẹ́lẹ̀ fún Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n ń rí ìran àlàáfíà fún un, nígbà tí kò sí àlàáfíà,”’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
17 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, dojú kọ àwọn ọmọbìnrin àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n ń hùmọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tiwọn, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí wọn. 18 Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ gbé ẹ̀yin obìnrin tó ń rán ìfúnpá fún gbogbo ọwọ́,* tí ẹ sì ń ṣe ìbòrí fún onírúurú orí kí ẹ lè dọdẹ ẹ̀mí* àwọn èèyàn! Ṣé ẹ̀mí* àwọn èèyàn mi ni ẹ̀ ń dọdẹ rẹ̀, tí ẹ wá ń dáàbò bo ẹ̀mí* tiyín? 19 Ṣé ẹ máa sọ mí di aláìmọ́ láàárín àwọn èèyàn mi torí ẹ̀kúnwọ́ ọkà bálì àti èérún búrẹ́dì?+ Ẹ̀ ń pa àwọn* tí kò yẹ kí ẹ pa, ẹ sì ń dá àwọn* tí kò yẹ kí wọ́n wà láàyè sí nípa irọ́ tí ẹ̀ ń pa fún àwọn èèyàn mi, tí àwọn náà sì ń fetí sí i.”’+
20 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Ẹ̀yin obìnrin yìí, mo kórìíra àwọn ìfúnpá yín tí ẹ fi ń dọdẹ àwọn èèyàn* bíi pé wọ́n jẹ́ ẹyẹ, èmi yóò já a kúrò ní ọwọ́ yín, èmi yóò sì tú àwọn tí ẹ̀ ń dọdẹ wọn bí ẹyẹ sílẹ̀. 21 Èmi yóò fa ìbòrí yín ya, màá sì gba àwọn èèyàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ yín, ẹ ò ní lè dọdẹ wọn mọ́; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+ 22 Torí ẹ ti fi èké ba olódodo lọ́kàn jẹ́,+ nígbà tí èmi kò bà á nínú jẹ́,* ẹ sì ti ki ẹni burúkú láyà,+ kó má bàa fi iṣẹ́ burúkú rẹ̀ sílẹ̀, kó lè wà láàyè.+ 23 Torí náà, ẹ̀yin obìnrin yìí ò ní rí ìran èké mọ́, ẹ ò sì ní woṣẹ́+ mọ́; èmi yóò gba àwọn èèyàn mi lọ́wọ́ yín, ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”
14 Àwọn kan lára àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì jókòó síwájú mi.+ 2 Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 3 “Ọmọ èèyàn, àwọn ọkùnrin yìí ti pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* wọn, wọ́n sì ti ṣe ohun ìkọ̀sẹ̀ tó ń mú kí àwọn èèyàn dẹ́ṣẹ̀. Ṣé kí n jẹ́ kí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?+ 4 Bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá pinnu láti tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀, tó ṣe ohun ìkọ̀sẹ̀ tó ń mú kí àwọn èèyàn dẹ́ṣẹ̀, tó sì wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ wòlíì, èmi Jèhófà yóò dá a lóhùn bó ṣe yẹ, bí òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀ bá ṣe pọ̀ tó. 5 Màá mú kí ẹ̀rù ba àwọn èèyàn ilé Ísírẹ́lì,* torí gbogbo wọn ti kẹ̀yìn sí mi, wọ́n sì ti tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.”’+
6 “Torí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ pa dà wá, ẹ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín sílẹ̀, kí ẹ sì yíjú kúrò nínú gbogbo ohun ìríra tí ẹ̀ ń ṣe.+ 7 Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tàbí àjèjì kan tó ń gbé ní Ísírẹ́lì bá kẹ̀yìn sí mi, tó sì pinnu láti tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀, tó ṣe ohun ìkọ̀sẹ̀ tó ń mú kí àwọn èèyàn dẹ́ṣẹ̀, tó wá lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ wòlíì mi,+ èmi Jèhófà yóò dá a lóhùn fúnra mi. 8 Màá gbéjà ko ọkùnrin náà, màá fi ṣe àmì àti ẹni àfipòwe, màá sì pa á run láàárín àwọn èèyàn mi;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’
9 “‘Àmọ́ tí a bá tan wòlíì náà, tó sì fún un lésì, èmi Jèhófà ló tàn án.+ Màá wá na ọwọ́ mi kí n lè fìyà jẹ ẹ́, màá sì pa á run kúrò láàárín àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì. 10 Wọ́n á ru ẹ̀bi wọn; ẹni tó lọ wádìí ọ̀rọ̀ àti wòlíì náà yóò jẹ̀bi ohun kan náà, 11 kí ilé Ísírẹ́lì má bàa kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́, kí wọ́n má sì fi ẹ̀ṣẹ̀ sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin mọ́. Wọ́n á di èèyàn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
12 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 13 “Ọmọ èèyàn, tí ilẹ̀ kan bá hùwà àìṣòótọ́ tó sì wá ṣẹ̀ mí, màá na ọwọ́ mi kí n lè fìyà jẹ ẹ́, màá sì dáwọ́ oúnjẹ rẹ̀ dúró.*+ Màá mú kí ìyàn mú níbẹ̀,+ màá sì pa èèyàn àti ẹranko inú rẹ̀ run.”+ 14 “‘Bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí bá tiẹ̀ wà níbẹ̀, Nóà,+ Dáníẹ́lì+ àti Jóòbù,+ ara wọn* nìkan ni wọ́n á lè gbà là torí òdodo+ wọn,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
15 “‘Tàbí ká ní mo mú kí àwọn ẹranko burúkú wọ ilẹ̀ náà, tí wọ́n pa àwọn èèyàn ibẹ̀,* tí wọ́n sì mú kí ilẹ̀ náà di ahoro, tí ẹnì kankan ò sì lè gba ibẹ̀ kọjá torí àwọn ẹranko tó wà níbẹ̀,+ 16 bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, tí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí bá tiẹ̀ wà níbẹ̀, wọn ò ní lè gba àwọn ọmọ wọn ọkùnrin tàbí ọmọ wọn obìnrin là; ara wọn nìkan ni wọ́n á gbà là, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro.’”
17 “‘Tàbí ká ní mo fi idà bá ilẹ̀ náà jà,+ tí mo sì sọ pé: “Kí idà lọ káàkiri ilẹ̀ náà,” tí mo sì pa èèyàn àti ẹranko inú rẹ̀ run,+ 18 tí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí bá tiẹ̀ wà níbẹ̀, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘wọn ò ní lè gba àwọn ọmọ wọn ọkùnrin tàbí ọmọ wọn obìnrin là; ara wọn nìkan ni wọ́n á gbà là.’”
19 “‘Tàbí ká ní mo fi àjàkálẹ̀ àrùn kọ lu ilẹ̀ náà,+ tí mo sì fi ìbínú ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀, kí n lè run èèyàn àti ẹranko inú rẹ̀, 20 tí Nóà,+ Dáníẹ́lì+ àti Jóòbù+ bá tiẹ̀ wà níbẹ̀, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘wọn ò ní lè gba àwọn ọmọ wọn ọkùnrin tàbí ọmọ wọn obìnrin là; ara wọn* nìkan ni wọ́n á gbà là torí òdodo+ wọn.’”
21 “Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Bó ṣe máa rí nìyẹn, nígbà tí mo bá fi oríṣi ìyà mẹ́rin*+ jẹ Jerúsálẹ́mù, ìyẹn idà, ìyàn, àwọn ẹranko burúkú àti àjàkálẹ̀ àrùn,+ kí n lè pa èèyàn àti ẹranko inú rẹ̀ run.+ 22 Àmọ́ àwọn kan tó ṣẹ́ kù nínú rẹ̀ yóò yè bọ́, wọ́n á sì mú wọn jáde,+ àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Wọ́n ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín, tí ẹ bá sì rí ìwà àti ìṣe wọn, àjálù tí mo mú wá sórí Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ohun tí mo ṣe sí i máa tù yín nínú.’”
23 “‘Tí ẹ bá rí ìwà àti ìṣe wọn, ó máa tù yín nínú, ẹ ó sì mọ̀ pé ó nídìí tí mo fi ṣe ohun tí mo ṣe sí i,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
15 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, ọ̀nà wo ni igi àjàrà gbà jọ àwọn igi yòókù tàbí àwọn ẹ̀ka igi inú igbó? 3 Ǹjẹ́ igi rẹ̀ wúlò fún iṣẹ́ kankan? Àbí àwọn èèyàn lè fi igi rẹ̀ ṣe èèkàn tí wọ́n á máa fi nǹkan kọ́? 4 Wò ó! Wọ́n fi dáná, iná jó o lórí àti ní ìdí, àárín rẹ̀ sì gbẹ. Ṣé ó wá wúlò fún iṣẹ́ kankan báyìí? 5 Nígbà tó ṣì wà lódindi, kò wúlò fún ohunkóhun. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ìgbà tí iná jó o, tó sì gbẹ!”
6 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Bí igi àjàrà láàárín àwọn igi inú igbó, tí mo ti sọ di ohun ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.+ 7 Mo ti gbéjà kò wọ́n. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ iná, síbẹ̀ iná máa jó wọn run. Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, nígbà tí mo bá gbéjà kò wọ́n.’”+
8 “‘Èmi yóò sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro,+ torí pé wọ́n ti hùwà àìṣòótọ́,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
16 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ ohun ìríra tí Jerúsálẹ́mù ń ṣe fún un.+ 3 Kí o sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún Jerúsálẹ́mù nìyí: “Ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì lo ti wá, ibẹ̀ ni wọ́n sì bí ọ sí. Ọmọ Ámórì+ ni bàbá rẹ, ọmọ Hétì+ sì ni ìyá rẹ. 4 Nígbà ìbí rẹ, ní ọjọ́ tí wọ́n bí ọ, wọn ò gé ìwọ́ rẹ, wọn ò fi omi wẹ̀ ọ́ kí ara rẹ lè mọ́, wọn ò fi iyọ̀ pa ọ́ lára, wọn ò sì fi aṣọ wé ọ. 5 Kò sẹ́ni tó káàánú rẹ débi tí wọ́n á ṣe ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí fún ọ. Kò sẹ́ni tó yọ́nú sí ọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, pápá gbalasa ni wọ́n jù ọ́ sí torí wọ́n kórìíra rẹ* ní ọjọ́ tí wọ́n bí ọ.
6 “‘“Nígbà tí mò ń kọjá lọ, mo rí ọ tí ò ń yí kiri nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, bí o sì ṣe wà níbẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sọ pé, ‘Máa wà láàyè!’ Àní mo sọ fún ọ bí o ṣe wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ pé, ‘Máa wà láàyè!’ 7 Mo mú kí o pọ̀ níye, bí àwọn ewéko tó ń hù ní oko, o dàgbà, o lára, o sì wọ ohun ọ̀ṣọ́ tó dára jù. Àwọn ọmú rẹ yọ dáadáa, irun rẹ sì hù; àmọ́ o ṣì wà ní ìhòòhò.”’
8 “‘Nígbà tí mò ń kọjá lọ tí mo rí ọ, mo rí i pé o ti dàgbà tó ẹni tí wọ́n ń kọnu ìfẹ́ sí. Mo wá fi aṣọ* mi bò ọ́,+ mo fi bo ìhòòhò rẹ, mo búra, mo sì bá ọ dá májẹ̀mú,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘o sì di tèmi. 9 Mo tún fi omi wẹ̀ ọ́, mo ṣan ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ, mo sì fi òróró pa ọ́ lára.+ 10 Mo wá fi aṣọ tí wọ́n kó iṣẹ́ sí wọ̀ ẹ́, mo fún ọ ní bàtà awọ* tó dáa, mo fi aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa wé ọ, mo sì wọ aṣọ olówó iyebíye fún ọ. 11 Mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà sí ọ lọ́wọ́, mo sì fi ìlẹ̀kẹ̀ sí ọ lọ́rùn. 12 Mo tún fi òrùka sí ọ nímú, mo fi yẹtí sí ọ létí, mo sì dé ọ ládé tó rẹwà. 13 Ò ń fi wúrà àti fàdákà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́, o wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa, aṣọ olówó iyebíye àti aṣọ tí wọ́n kó iṣẹ́ sí. O jẹ ìyẹ̀fun tó kúnná, oyin àti òróró, o ti wá rẹwà gan-an,+ o sì ti yẹ láti di ayaba.’”*
14 “‘Òkìkí rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í kàn* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè+ torí ẹwà rẹ, ẹwà rẹ kò lábùlà torí èmi ni mo dá ọ lọ́lá,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
15 “‘Àmọ́ ẹwà rẹ mú kí o bẹ̀rẹ̀ sí í jọ ara rẹ lójú,+ o sì di aṣẹ́wó torí òkìkí rẹ ti kàn káàkiri.+ Gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ lo bá ṣèṣekúṣe,+ ẹwà rẹ sì di tiwọn. 16 O mú lára àwọn ẹ̀wù rẹ, o sì ṣe àwọn ibi gíga aláràbarà tí o ti ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+ Kò yẹ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wáyé, kò tiẹ̀ yẹ kó ṣẹlẹ̀ rárá. 17 O tún mú ohun ọ̀ṣọ́ wúrà àti fàdákà tí mo fún ọ, o fi ṣe àwọn ère ọkùnrin fún ara rẹ, o sì bá wọn ṣèṣekúṣe.+ 18 O fi aṣọ rẹ tí wọ́n kó iṣẹ́ sí bò wọ́n,* o sì fi òróró àti tùràrí mi rúbọ sí wọn.+ 19 Búrẹ́dì tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná, òróró àti oyin ṣe tí mo fún ọ pé kí o jẹ, lo tún fi rúbọ olóòórùn dídùn* sí wọn.+ Ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan nìyẹn,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
20 “‘O fi àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin tí o bí fún mi+ rúbọ sí àwọn òrìṣà.+ Ṣé ohun kékeré lo pe iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ò ń ṣe ni? 21 O pa àwọn ọmọ mi, o sì sun wọ́n nínú iná láti fi wọ́n rúbọ.+ 22 Bí o ṣe ń lọ́wọ́ nínú àwọn ohun ìríra tí o sì ń ṣèṣekúṣe, o ò rántí ìgbà tí o ṣì kéré tí o sì wà ní ìhòòhò, tí ò ń yí kiri nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ. 23 O gbé, o gbé lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ ibi rẹ,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 24 ‘O mọ òkìtì fún ara rẹ, o sì kọ́ ibi gíga fún ara rẹ ní gbogbo ojúde ìlú. 25 Ibi tó gbàfiyèsí jù ní gbogbo ojú ọ̀nà lo kọ́ àwọn ibi gíga rẹ sí, o sì sọ ẹwà rẹ di ohun ìríra bí o ṣe ń bá gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ ṣèṣekúṣe,*+ o sì wá jingíri sínú iṣẹ́ aṣẹ́wó.+ 26 O bá àwọn ọmọ Íjíbítì ṣèṣekúṣe,+ àwọn aládùúgbò rẹ oníṣekúṣe,* iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ tó bùáyà sì múnú bí mi. 27 Màá wá na ọwọ́ mi kí n lè fìyà jẹ ọ́, màá dín oúnjẹ tí ò ń rí gbà kù,+ màá mú kí àwọn obìnrin tó kórìíra rẹ,+ àwọn ọmọbìnrin Filísínì, ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́* sí ọ, àwọn tí ìwà àìnítìjú rẹ ń rí lára.+
28 “‘Torí kò tẹ́ ọ lọ́rùn, o tún bá àwọn ọmọ Ásíríà ṣèṣekúṣe.+ Síbẹ̀ ìṣekúṣe tí o bá wọn ṣe yẹn kò tẹ́ ọ lọ́rùn. 29 O tún lọ ṣèṣekúṣe ní ilẹ̀ àwọn oníṣòwò* àti lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà,+ síbẹ̀, kò tẹ́ ọ lọ́rùn. 30 Wo bí àárẹ̀* ṣe mú ọkàn rẹ tó,’* ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘nígbà tí o ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, tí ò ń hùwà bí aṣẹ́wó tí kò nítìjú!+ 31 Àmọ́ nígbà tí o mọ òkìtì rẹ sí ibi tó gbàfiyèsí jù ní gbogbo ojú ọ̀nà, tí o sì kọ́ ibi gíga rẹ sí gbogbo ojúde ìlú, ìwọ ò dà bí aṣẹ́wó torí o ò gba owó kankan. 32 Alágbèrè obìnrin tó ń tẹ̀ lé àwọn àjèjì dípò ọkọ rẹ̀ ni ọ́!+ 33 Àwọn èèyàn ló máa ń fún aṣẹ́wó lẹ́bùn+ àmọ́ ìwọ lò ń fún gbogbo àwọn tó ń bá ọ ṣèṣekúṣe lẹ́bùn,+ o tún fún wọn ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n lè wá bá ọ ṣèṣekúṣe láti ibi gbogbo.+ 34 O yàtọ̀ sí àwọn obìnrin míì tó ń ṣe aṣẹ́wó. Kò sí ẹni tó ń ṣe aṣẹ́wó bíi tìẹ! Ò ń san owó fún àwọn ẹlòmíì, àwọn kò sì sanwó fún ọ. O yàtọ̀ sí wọn pátápátá.’
35 “Torí náà, gbọ́ ohun tí Jèhófà sọ, ìwọ aṣẹ́wó.+ 36 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí pé ìṣekúṣe rẹ ti hàn sí gbangba, ìhòòhò rẹ sì ti hàn síta nígbà tí ò ń bá àwọn olólùfẹ́ rẹ ṣèṣekúṣe, tí o sì ń bá àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* rẹ+ tó ń ríni lára ṣèṣekúṣe, àwọn tí o tún fi ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ rúbọ sí,+ 37 torí náà, èmi yóò kó gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ tí ẹ jọ gbádùn ara yín jọ, gbogbo àwọn tí o fẹ́ràn àti àwọn tí o kórìíra. Màá kó wọn jọ láti ibi gbogbo kí wọ́n lè bá ọ jà, màá sì tú ọ sí ìhòòhò lójú wọn, wọ́n á sì rí ìhòòhò rẹ.+
38 “‘Màá dá ọ lẹ́jọ́ tó tọ́ sí àwọn alágbèrè obìnrin+ àti àwọn obìnrin tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,+ màá sì fi ìbínú àti owú ta ẹ̀jẹ̀ rẹ sílẹ̀.+ 39 Màá mú kí o kó sọ́wọ́ wọn, wọ́n á ya àwọn òkìtì rẹ lulẹ̀, wọ́n á sì wó àwọn ibi gíga rẹ;+ wọ́n á bọ́ aṣọ lára rẹ,+ wọ́n á gba ohun ọ̀ṣọ́ rẹ tó rẹwà,+ wọ́n á sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò. 40 Wọn yóò kó èrò jọ láti bá ọ jà,+ wọ́n á sọ ọ́ ní òkúta,+ wọ́n á sì fi idà wọn pa ọ́.+ 41 Wọn yóò dáná sun àwọn ilé rẹ,+ wọ́n á sì dá ọ lẹ́jọ́ níṣojú ọ̀pọ̀ obìnrin; èmi yóò fòpin sí iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ,+ o ò sì ní san owó fún wọn mọ́. 42 Màá bínú sí ọ débi tó máa tẹ́ mi lọ́rùn,+ mi ò wá ní bínú sí ọ mọ́;+ ìbínú mi á rọlẹ̀, ohun tí o ṣe ò sì ní dùn mí mọ́.’
43 “‘Torí pé o ò rántí ìgbà èwe rẹ,+ tí gbogbo ohun tí o ṣe yìí sì múnú bí mi, màá fi ìwà rẹ san ọ́ lẹ́san,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘o ò ní hùwà àìnítìjú, o ò sì ní ṣe ohun tó ń ríni lára mọ́.
44 “‘Wò ó! Gbogbo ẹni tó ń sọ̀rọ̀ lówelówe yóò pa òwe yìí fún ọ pé: “Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin rẹ̀ rí!”+ 45 Ọmọbìnrin ìyá rẹ ni ọ́, ẹni tó kórìíra ọkọ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Arábìnrin lo sì jẹ́ sí àwọn ọmọ ìyá rẹ lóbìnrin, àwọn tó kórìíra ọkọ àti àwọn ọmọ wọn. Ọmọ Hétì ni ìyá rẹ, ọmọ Ámórì+ sì ni bàbá rẹ.’”
46 “‘Samáríà ni ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin,+ tí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin* ń gbé ní àríwá rẹ.*+ Sódómù+ sì ni àbúrò rẹ obìnrin, tí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin ń gbé ní gúúsù rẹ.*+ 47 Kì í ṣe pé o rìn ní ọ̀nà wọn, tí o sì bá wọn ṣe àwọn ohun ìríra wọn nìkan ni, àmọ́ láàárín àkókò díẹ̀, ìwà ìbàjẹ́ tí ò ń hù nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ burú ju tiwọn lọ.+ 48 Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Sódómù arábìnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin kò ṣe ohun tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ obìnrin ti ṣe. 49 Wò ó! Àṣìṣe tí Sódómù arábìnrin rẹ ṣe ni pé: Òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin+ gbéra ga,+ wọ́n ní oúnjẹ rẹpẹtẹ,+ ara tù wọ́n;+ síbẹ̀ wọn ò ran àwọn tí ìyà ń jẹ àti tálákà lọ́wọ́.+ 50 Wọn ò yéé gbéra ga,+ wọ́n sì ń ṣe ohun ìríra níṣojú mi,+ torí náà, mo rí i pé ó yẹ kí n mú wọn kúrò.+
51 “‘Ẹ̀ṣẹ̀ Samáríà+ kò tiẹ̀ tó ìdajì tìrẹ. Ṣe ni ohun ìríra tí ò ń ṣe ń pọ̀ sí i, débi pé gbogbo ohun ìríra tí ò ń ṣe mú kí àwọn arábìnrin rẹ dà bí olódodo.+ 52 Ó yẹ kí ojú tì ọ́ báyìí torí ìwà rẹ ti dá àwọn arábìnrin rẹ láre.* Torí ẹ̀ṣẹ̀ tí o dá ń ríni lára ju tiwọn lọ, òdodo wọn ju tìrẹ lọ. Ní báyìí, kí o tẹ́, kí ojú sì tì ọ́ torí o mú kí àwọn arábìnrin rẹ dà bí olódodo.’
53 “‘Èmi yóò kó àwọn ẹrú wọn jọ, àwọn ẹrú Sódómù àtàwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin àti àwọn ẹrú Samáríà àtàwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin; màá sì kó àwọn ẹrú tìrẹ náà jọ,+ 54 kí o lè tẹ́; kí ojú sì tì ọ́ torí ohun tí o ti ṣe, bí o ṣe mú kí ara tù wọ́n. 55 Àwọn arábìnrin rẹ, Sódómù àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, yóò pa dà sí bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀, Samáríà àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin yóò pa dà sí bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ obìnrin yóò sì pa dà sí bí ẹ ṣe wà tẹ́lẹ̀.+ 56 Ní ọjọ́ tí o gbé ara rẹ ga, o ka Sódómù arábìnrin rẹ sí ẹni tí kò yẹ kí o máa sọ̀rọ̀ rẹ̀, 57 kó tó di pé ìwà burúkú rẹ hàn síta.+ Àwọn ọmọbìnrin Síríà àti àwọn tó wà ní agbègbè wọn wá ń kẹ́gàn rẹ, àwọn ọmọbìnrin Filísínì,+ àwọn tó yí ọ ká sì ń fi ọ́ ṣẹlẹ́yà. 58 O máa jìyà ìwà àìnítìjú rẹ àti àwọn ohun ìríra tí o ṣe,’ ni Jèhófà wí.”
59 “Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Ní báyìí, ohun tí o ṣe sí mi ni màá fi hùwà sí ọ,+ torí o fojú kéré ìbúra tí o ṣe ní ti pé o da májẹ̀mú mi.+ 60 Àmọ́ èmi yóò rántí májẹ̀mú tí mo bá ọ dá nígbà èwe rẹ, màá sì bá ọ dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé.+ 61 Ìwọ yóò rántí ìwà rẹ, ojú á sì tì ọ́+ nígbà tí o bá gba àwọn arábìnrin rẹ, àwọn ẹ̀gbọ́n àti àwọn àbúrò rẹ, èmi yóò sì fi wọ́n fún ọ bí ọmọbìnrin, àmọ́ kì í ṣe torí májẹ̀mú rẹ.’
62 “‘Èmi yóò fìdí májẹ̀mú tí mo bá ọ dá múlẹ̀; ìwọ yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà. 63 Nígbà tí mo bá dárí jì ọ́* láìka gbogbo ohun tí o ti ṣe sí,+ wàá rántí, ìtìjú ò sì ní jẹ́ kí o lè la ẹnu rẹ+ torí pé o ti tẹ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
17 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, pa àlọ́, kí o sì pa òwe nípa ilé Ísírẹ́lì.+ 3 Kí o sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹyẹ idì ńlá+ kan wá sí Lẹ́bánónì,+ apá rẹ̀ tóbi, ìyẹ́ rẹ̀ gùn, ìyẹ́ náà kún ara rẹ̀, ó sì ní àwọ̀ aláràbarà. Idì náà sì ṣẹ́ téńté orí igi kédárì.+ 4 Ó já ọ̀mùnú rẹ̀ tó wà lókè pátápátá, ó mú un wá sí ilẹ̀ àwọn oníṣòwò,* ó sì gbìn ín sí ìlú àwọn oníṣòwò.+ 5 Ó wá mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà,+ ó sì fi sínú ilẹ̀ tó lọ́ràá. Ó gbìn ín bí igi wílò lẹ́gbẹ̀ẹ́ alagbalúgbú omi. 6 Ó rú jáde, ó sì di àjàrà tí kò ga, tó bolẹ̀,+ tí ewé rẹ̀ kò nà jáde, tí gbòǹgbò rẹ̀ sì ń hù lábẹ́ rẹ̀. Ó wá di àjàrà, ó yọ ọ̀mùnú, ó sì pẹ̀ka.+
7 “‘“Ẹyẹ idì ńlá mìíràn tún wá,+ apá rẹ̀ tóbi, ìyẹ́ rẹ̀ sì fẹ̀.+ Àjàrà yìí yára na gbòǹgbò rẹ̀ kúrò nínú ọgbà tí wọ́n gbìn ín sí lọ sọ́dọ̀ ẹyẹ idì náà, ó sì na àwọn ewé rẹ̀ sọ́dọ̀ ẹyẹ náà kó lè bomi rin ín.+ 8 Inú oko tó dára, lẹ́gbẹ̀ẹ́ alagbalúgbú omi ni wọ́n gbìn ín sí, kó lè yọ ẹ̀ka, kó lè so èso, kó sì di àjàrà ńlá.”’+
9 “Sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ǹjẹ́ ó máa gbèrú? Ṣé ẹnì kan ò ní fa gbòǹgbò rẹ̀ tu+ tàbí kó mú kí èso rẹ̀ jẹrà, kó sì mú kí ọ̀mùnú rẹ̀ rọ?+ Yóò gbẹ débi pé kò ní nílò ọwọ́ tó lágbára tàbí ọ̀pọ̀ èèyàn kí wọ́n tó lè fà á tu tegbòtegbò. 10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tún un gbìn, ǹjẹ́ ó máa gbèrú? Ṣé kò ní gbẹ dà nù nígbà tí atẹ́gùn ìlà oòrùn bá fẹ́ lù ú? Yóò gbẹ dà nù lórí ebè tó hù sí.”’”
11 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 12 “Jọ̀ọ́ sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé náà pé, ‘Ṣé ẹ ò mọ ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí ni?’ Sọ pé, ‘Wò ó! Ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó mú ọba rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì mú wọn pa dà wá sí Bábílónì.+ 13 Ó tún mú ọ̀kan lára àwọn ọmọ* ọba,+ ó bá a dá májẹ̀mú, ó sì mú kó búra.+ Ó wá kó àwọn tó gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ náà lọ,+ 14 kó lè rẹ ìjọba náà wálẹ̀, kó má lè dìde, kó lè jẹ́ pé tó bá ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ nìkan ni ìjọba náà á fi lè máa wà nìṣó.+ 15 Àmọ́ níkẹyìn, ọba náà ṣọ̀tẹ̀ sí i,+ ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí Íjíbítì, kí wọ́n lè fún un ní àwọn ẹṣin+ àti ọmọ ogun púpọ̀.+ Ṣé ó máa ṣàṣeyọrí? Ǹjẹ́ ẹni tó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí á bọ́ lọ́wọ́ ìyà? Ṣé ó lè da májẹ̀mú kó sì mú un jẹ?’+
16 “‘“Bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, “Bábílónì ni yóò kú sí, níbi tí ọba* tó fi í* jọba ń gbé, ẹni tí òun kò ka ìbúra rẹ̀ sí, tó sì da májẹ̀mú rẹ̀.+ 17 Ẹgbẹ́ ogun Fáráò àti àwọn ọmọ ogun wọn kò ní lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ogun,+ nígbà tí wọ́n bá mọ òkìtì láti dó tì í, tí wọ́n sì mọ odi kí wọ́n lè gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn.* 18 Ó ti fojú kéré ìbúra, ó sì ti da májẹ̀mú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣèlérí,* ó ti ṣe gbogbo nǹkan yìí, kò sì ní yè bọ́.”’
19 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Bí mo ti wà láàyè, èmi yóò fìyà ohun tó ṣe jẹ ẹ́, bó ṣe fojú kéré ìbúra mi+ tó sì da májẹ̀mú mi. 20 Èmi yóò ju àwọ̀n mi sí i láti fi mú un.+ Èmi yóò mú un wá sí Bábílónì, màá sì dá a lẹ́jọ́ níbẹ̀ torí ìwà àìṣòótọ́ tó hù sí mi.+ 21 Idà ni yóò pa gbogbo àwọn tó bá sá lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn yòókù á sì fọ́n ká síbi gbogbo.*+ Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.”’+
22 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú ọ̀mùnú ní téńté orí igi kédárì tó ga fíofío,+ màá sì gbìn ín, láti orí ẹ̀ka igi rẹ̀ ni èmi yóò ti já ọ̀mùnú múlọ́múlọ́,+ màá sì gbìn ín sórí òkè tó ga fíofío.+ 23 Èmi yóò gbìn ín sórí òkè tó ga ní Ísírẹ́lì; yóò yọ ẹ̀ka, yóò so èso, yóò sì di igi kédárì ńlá. Oríṣiríṣi ẹyẹ yóò máa gbé lábẹ́ rẹ̀, wọ́n á sì fi òjìji àwọn ewé rẹ̀ ṣe ibùgbé wọn. 24 Gbogbo igi oko yóò sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti rẹ igi ńlá wálẹ̀, mo sì ti gbé igi tó rẹlẹ̀ ga;+ mo ti sọ igi tútù di gbígbẹ, mo sì ti mú kí igi tó gbẹ rúwé.+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀, mo sì ti ṣe é.”’”
18 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Kí ni òwe tí ẹ̀ ń pa ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì yìí túmọ̀ sí, pé, ‘Àwọn bàbá ti jẹ èso àjàrà tí kò pọ́n, àmọ́ àwọn ọmọ ni eyín ń kan’?+
3 “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘ẹ ò ní pa òwe yìí mọ́ ní Ísírẹ́lì. 4 Wò ó! Gbogbo ọkàn,* tèmi ni wọ́n. Bí ọkàn bàbá ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ. Ọkàn* tó bá ṣẹ̀ ni yóò kú.
5 “‘Ká ní ọkùnrin kan wà tó jẹ́ olódodo, tó sì máa ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ. 6 Kì í jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òrìṣà lórí àwọn òkè;+ kò gbójú lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* ilé Ísírẹ́lì, kì í bá ìyàwó ọmọnìkejì rẹ̀ sùn+ tàbí kó bá obìnrin tó ń ṣe nǹkan oṣù ní àṣepọ̀;+ 7 kì í ni ẹnikẹ́ni lára,+ àmọ́ ó máa ń dá ohun tí ẹni tó jẹ ẹ́ ní gbèsè fi ṣe ìdúró pa dà fún un;+ kì í ja ẹnikẹ́ni lólè,+ àmọ́ ó máa ń gbé oúnjẹ rẹ̀ fún ẹni tí ebi ń pa,+ ó sì máa ń da aṣọ bo ẹni tó wà níhòòhò;+ 8 kì í yáni lówó èlé, kì í sì í gba èlé gọbọi lórí owó tó yáni,+ kì í rẹ́ni jẹ;+ ẹjọ́ òdodo ló máa ń dá láàárín ẹni méjì;+ 9 ó ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ó sì ń tẹ̀ lé ìdájọ́ mi kó lè jẹ́ olóòótọ́. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ olódodo, ó sì dájú pé yóò máa wà láàyè,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
10 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ó ní ọmọ kan tó ń jalè+ tàbí tó jẹ́ apààyàn*+ tàbí tó ń ṣe èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan yìí 11 (bí bàbá rẹ̀ ò bá tiẹ̀ lọ́wọ́ nínú nǹkan wọ̀nyí), tó ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òrìṣà lórí àwọn òkè, tó ń bá ìyàwó ọmọnìkejì rẹ̀ sùn, 12 tó ń ni aláìní àti tálákà lára,+ tó ń jalè, tí kì í dá ohun tí wọ́n fi ṣe ìdúró pa dà, tó gbójú lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin,+ tó ń ṣe àwọn ohun ìríra,+ 13 tó ń gba èlé gọbọi lórí owó tó yáni, tó sì ń yáni lówó èlé,+ ọmọ náà kò ní wà láàyè. Ṣe ni wọ́n máa pa á, torí gbogbo ohun ìríra tó ti ṣe. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní ọrùn rẹ̀.
14 “Àmọ́ ká ní bàbá kan ní ọmọ, tó ń rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí bàbá rẹ̀ ti dá, àmọ́ tí kò ṣe bíi bàbá rẹ̀, bó tiẹ̀ ń rí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà. 15 Kì í jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òrìṣà lórí àwọn òkè; kò gbójú lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin ilé Ísírẹ́lì, kì í bá ìyàwó ọmọnìkejì rẹ̀ sùn; 16 kì í ni ẹnikẹ́ni lára, kì í gbẹ́sẹ̀ lé ohun tí wọ́n fi ṣe ìdúró; kì í jalè rárá; ó máa ń gbé oúnjẹ rẹ̀ fún ẹni tí ebi ń pa, ó sì máa ń da aṣọ bo ẹni tó wà níhòòhò; 17 kì í ni àwọn aláìní lára; kì í gba èlé gọbọi lórí owó tó yáni, kì í sì í yáni lówó èlé; ó ń tẹ̀ lé ìdájọ́ mi; ó sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ bàbá rẹ̀. Ó dájú pé yóò máa wà láàyè. 18 Àmọ́ torí pé oníjìbìtì ni bàbá rẹ̀, tó ja arákùnrin rẹ̀ lólè, tó sì ṣe ohun tí kò dáa láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, bàbá náà yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
19 “‘Àmọ́ ìwọ á sọ pé: “Kí nìdí tí ọmọ ò fi ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ bàbá rẹ̀?” Nítorí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó jẹ́ òdodo, tó pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, tó sì ń tẹ̀ lé e, ó dájú pé yóò máa wà láàyè.+ 20 Ọkàn* tó bá ṣẹ̀ ni yóò kú.+ Ọmọ ò ní ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ bàbá rẹ̀, bàbá ò sì ní ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ rẹ̀. Olódodo máa jèrè òdodo rẹ̀, ẹni burúkú sì máa jèrè ìwà burúkú rẹ̀.+
21 “‘Àmọ́, bí ẹni burúkú bá yí pa dà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá, tó ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tó ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó jẹ́ òdodo, ó dájú pé yóò máa wà láàyè. Kò ní kú.+ 22 Mi ò ní ka* gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sí i lọ́rùn.+ Yóò máa wà láàyè torí ó ń ṣe òdodo.’+
23 “‘Ǹjẹ́ inú mi máa ń dùn sí ikú ẹni burúkú?’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Ṣebí ohun tí mo fẹ́ ni pé kó yí ìwà rẹ̀ pa dà kó sì máa wà láàyè?’+
24 “‘Àmọ́ tí olódodo bá fi òdodo tó ń ṣe sílẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa,* tó ń ṣe gbogbo ohun ìríra tí àwọn ẹni burúkú ń ṣe, ǹjẹ́ ó máa wà láàyè? Mi ò ní rántí ìkankan nínú gbogbo iṣẹ́ òdodo rẹ̀.+ Yóò kú torí ìwà àìṣòótọ́ rẹ̀ àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá.+
25 “‘Àmọ́ ẹ̀yin á sọ pé: “Ọ̀nà Jèhófà kò tọ́.”+ Jọ̀ọ́ fetí sílẹ̀, ìwọ ilé Ísírẹ́lì! Ṣé ọ̀nà mi ni ò tọ́?+ Ṣebí ọ̀nà tiyín ni kò tọ́?+
26 “‘Tí olódodo bá fi òdodo tó ń ṣe sílẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa, tó sì kú nítorí àìdáa tó ṣe, ikú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ló kú.
27 “‘Àmọ́ tí ẹni burúkú bá yí pa dà kúrò nínú iṣẹ́ ibi tó ti ṣe, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó jẹ́ òdodo, ó máa dá ẹ̀mí* rẹ̀ sí.+ 28 Tó bá sì wá mọ̀, tó sì yí pa dà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá, ó dájú pé yóò máa wà láàyè. Kò ní kú.
29 “‘Àmọ́ ilé Ísírẹ́lì á sọ pé: “Ọ̀nà Jèhófà kò tọ́.” Ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ṣé òótọ́ ni pé ọ̀nà mi ni ò tọ́?+ Ṣebí ọ̀nà tiyín ni kò tọ́?’
30 “‘Torí náà, màá fi ìwà yín dá kálukú yín lẹ́jọ́,+ ilé Ísírẹ́lì,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Ẹ yí pa dà, àní ẹ yí pa dà pátápátá kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí wọ́n má bàa di ohun ìkọ̀sẹ̀ tó máa mú kí ẹ jẹ̀bi. 31 Ẹ jáwọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín,+ kí ẹ sì ní* ọkàn tuntun àti ẹ̀mí tuntun.+ Ṣé ó wá yẹ kí ẹ kú,+ ilé Ísírẹ́lì?’
32 “‘Inú mi ò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Torí náà, ẹ yí pa dà, kí ẹ sì máa wà láàyè.’”+
19 “Kí o kọ orin arò* nípa àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, 2 kí o sì sọ pé,
‘Ta ni ìyá rẹ? Abo kìnnìún láàárín àwọn kìnnìún.
Ó dùbúlẹ̀ sáàárín àwọn ọmọ kìnnìún tó lágbára,* ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
3 Ó tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di ọmọ kìnnìún tó lágbára.+
Ọmọ náà kọ́ bí wọ́n ṣe ń pa ẹran jẹ,
Ó tún ń pa èèyàn jẹ.
4 Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n mú un nínú ihò wọn,
Wọ́n sì fi ìkọ́ fà á wá sí ilẹ̀ Íjíbítì.+
5 Ìyá rẹ̀ dúró dè é, nígbà tó yá, ó rí i pé kò sírètí pé ó máa pa dà.
Torí náà, ó mú òmíràn nínú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì rán an jáde bí ọmọ kìnnìún tó lágbára.
6 Òun náà rìn káàkiri láàárín àwọn kìnnìún, ó sì di ọmọ kìnnìún tó lágbára.
Ó kọ́ bí wọ́n ṣe ń pa ẹran jẹ, ó sì tún ń pa èèyàn jẹ.+
7 Ó ń rìn kiri láàárín àwọn ilé gogoro wọn tó láàbò, ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro,
Débi pé ìró bó ṣe ń ké ramúramù gba ilẹ̀ tó ti di ahoro náà kan.+
8 Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láwọn agbègbè tó yí i ká wá a wá kí wọ́n lè fi àwọ̀n mú un,
Wọ́n sì mú un nínú ihò wọn.
9 Wọ́n fi ìkọ́ gbé e sínú àhámọ́, wọ́n sì gbé e wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì.
Ibẹ̀ ni wọ́n sé e mọ́, kí wọ́n má bàa gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì.
10 Ìyá rẹ dà bí àjàrà+ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ,* èyí tí wọ́n gbìn sétí omi.
Ọ̀pọ̀ omi náà mú kó so èso, kó sì pẹ̀ka rẹpẹtẹ.
11 Ó wá ní àwọn ẹ̀ka* tó lágbára, tó ṣeé fi ṣe ọ̀pá àṣẹ àwọn alákòóso.
Ó dàgbà, ó sì ga ju àwọn igi yòókù,
Wọ́n sì wá rí i, torí pé ó ga, ewé rẹ̀ sì pọ̀ yanturu.
12 Àmọ́ a fà á tu tìbínútìbínú,+ a sì jù ú sórí ilẹ̀,
Atẹ́gùn ìlà oòrùn sì mú kí èso rẹ̀ gbẹ.
Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó lágbára ya dà nù, wọ́n gbẹ,+ iná sì jó wọn run.+
13 Inú aginjù ni wọ́n wá gbìn ín sí,
Ní ilẹ̀ tó gbẹ, tí kò lómi.+
14 Iná ràn látorí àwọn ẹ̀ka rẹ̀, ó sì jó àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ àti àwọn èso rẹ̀,
Kò sì wá sí ẹ̀ka tó lágbára mọ́ lórí rẹ̀, kò sí ọ̀pá àṣẹ fún àwọn alákòóso.+
“‘Orin arò nìyẹn, yóò sì máa jẹ́ orin arò.’”
20 Ní ọdún keje, ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, àwọn kan lára àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì jókòó síwájú mi kí wọ́n lè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà. 2 Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 3 “Ọmọ èèyàn, bá àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ṣé ọ̀dọ̀ mi lẹ ti fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ ni? ‘Bí mo ti wà láàyè, mi ò ní dá yín lóhùn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’
4 “Ṣé o ṣe tán láti dá wọn lẹ́jọ́?* Ọmọ èèyàn, ṣé o ṣe tán láti dá wọn lẹ́jọ́? Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun ìríra tí àwọn baba ńlá wọn ṣe.+ 5 Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ní ọjọ́ tí mo yan Ísírẹ́lì,+ mo tún búra* fún ọmọ* ilé Jékọ́bù, mo sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ mí ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Àní, mo búra fún wọn, mo sì sọ pé, ‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’ 6 Ní ọjọ́ yẹn, mo búra fún wọn pé màá mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì lọ sí ilẹ̀ tí mo ṣàwárí* fún wọn, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ Ibi tó rẹwà* jù ní gbogbo ilẹ̀ náà. 7 Mo wá sọ fún wọn pé, ‘Kí kálukú yín ju ohun ìríra tó wà níwájú rẹ̀ nù; ẹ má fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* Íjíbítì sọ ara yín di ẹlẹ́gbin.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’+
8 “‘“Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, kò sì wù wọ́n láti fetí sí mi. Wọn ò ju ohun ìríra tó wà níwájú wọn nù, wọn ò sì fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin Íjíbítì sílẹ̀.+ Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn, inú mi á sì ru sí wọn gidigidi ní ilẹ̀ Íjíbítì. 9 Àmọ́, mo gbé ìgbésẹ̀ torí orúkọ mi, kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè, láàárín àwọn tí wọ́n ń gbé.+ Torí nígbà tí mo mú wọn* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mo jẹ́ kí wọ́n* mọ̀ mí níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè yìí.+ 10 Torí náà, mo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mo sì mú wọn wá sí aginjù.+
11 “‘“Mo wá fún wọn ní àwọn àṣẹ mi, mo sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ìdájọ́ mi,+ èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè.+ 12 Mo tún fún wọn ní àwọn sábáàtì mi,+ kó lè jẹ́ àmì láàárín èmi àti àwọn,+ kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń sọ wọ́n di mímọ́.
13 “‘“Àmọ́, ilé Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí mi ní aginjù.+ Wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, wọ́n sì kọ àwọn ìdájọ́ mi, èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè. Wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́ pátápátá. Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn nínú aginjù kí n lè pa wọ́n run.+ 14 Àmọ́, mo gbé ìgbésẹ̀ torí orúkọ mi, kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n rí i nígbà tí mo mú wọn* jáde.+ 15 Mo tún búra fún wọn nínú aginjù pé mi ò ní mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ibi tó rẹwà* jù ní gbogbo ilẹ̀ náà, 16 torí pé wọ́n kọ àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, wọ́n sì sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́ torí ọkàn wọn ń fà sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.+
17 “‘“Àmọ́ mo* ṣàánú wọn, mi ò sì pa wọ́n run; mi ò pa wọ́n rẹ́ ní aginjù. 18 Mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú aginjù pé,+ ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ pa ìlànà àwọn baba ńlá yín mọ́,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìdájọ́ wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn sọ ara yín di ẹlẹ́gbin. 19 Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. Ẹ máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, kí ẹ rìn nínú àwọn ìdájọ́ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́.+ 20 Ẹ sọ àwọn sábáàtì mi di mímọ́,+ kó sì jẹ́ àmì láàárín èmi àti ẹ̀yin, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’+
21 “‘“Àmọ́ àwọn ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+ Wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi mọ́, wọn ò tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò sì rìn nínú rẹ̀, èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè. Wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́. Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn, inú mi á sì ru sí wọn gidigidi ní aginjù.+ 22 Àmọ́ mi ò ṣe bẹ́ẹ̀,+ mo sì gbé ìgbésẹ̀ nítorí orúkọ mi,+ kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó rí i nígbà tí mo mú wọn* jáde. 23 Bákan náà, mo búra fún wọn nínú aginjù pé màá fọ́n wọn ká sí àwọn orílẹ̀-èdè, màá sì tú wọn ká sí àwọn ilẹ̀,+ 24 torí wọn ò pa àwọn ìdájọ́ mi mọ́, wọ́n sì kọ àwọn àṣẹ mi sílẹ̀,+ wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́, wọ́n sì ń tẹ̀ lé* àwọn òrìṣà ẹ̀gbin tí àwọn baba ńlá wọn ń sìn.+ 25 Mo tún gbà wọ́n láyè láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí kò dáa àti àwọn ìdájọ́ tí kò lè mú kí wọ́n wà láàyè.+ 26 Mo jẹ́ kí àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sọ wọ́n di aláìmọ́, bí wọ́n ṣe ń sun àwọn àkọ́bí ọmọ wọn nínú iná,+ kí n lè sọ wọ́n di ahoro, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’
27 “Torí náà, ọmọ èèyàn, bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Bí àwọn baba ńlá yín ṣe sọ̀rọ̀ òdì sí mi nìyẹn tí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí mi. 28 Mo mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo búra pé màá fún wọn.+ Nígbà tí wọ́n rí gbogbo òkè tó ga àti àwọn igi tí ewé kún orí rẹ̀,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ wọn, wọ́n sì ń mú àwọn ọrẹ wọn tó ń múnú bí mi lọ síbẹ̀. Wọ́n ń gbé àwọn ẹbọ wọn tó ní òórùn dídùn* lọ síbẹ̀, wọ́n sì ń da àwọn ọrẹ ohun mímu wọn sílẹ̀ níbẹ̀. 29 Mo wá bi wọ́n pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ ibi gíga tí ẹ̀ ń lọ yìí? (Wọ́n ṣì ń pè é ní Ibi Gíga títí dòní.)’”’+
30 “Kí o wá sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ṣé ẹ fẹ́ sọ ara yín di ẹlẹ́gbin bíi ti àwọn baba ńlá yín ni, tí wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn kí wọ́n lè bá wọn ṣe àgbèrè ẹ̀sìn?+ 31 Ṣé ẹ ṣì ń sọ ara yín di ẹlẹ́gbin títí dòní olónìí, tí ẹ̀ ń rúbọ sí gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin yín, tí ẹ̀ ń sun àwọn ọmọ yín nínú iná?+ Ṣé ó wá yẹ kí n dá yín lóhùn pẹ̀lú gbogbo ohun tí ẹ ṣe yìí, ilé Ísírẹ́lì?”’+
“‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘mi ò ní dá yín lóhùn.+ 32 Ohun tí ẹ sì ní lọ́kàn* nígbà tí ẹ̀ ń sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká dà bí àwọn orílẹ̀-èdè, bí àwọn ìdílé tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ míì, tí wọ́n ń jọ́sìn* igi àti òkúta,”+ kò ní ṣẹlẹ̀ láé.’”
33 “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘ọwọ́ agbára, apá tí mo nà jáde àti ìbínú ni màá fi ṣàkóso yín.+ 34 Èmi yóò mú yín jáde láàárín àwọn èèyàn, màá sì fi ọwọ́ agbára, apá tí mo nà jáde àti ìbínú kó yín jọ láti àwọn ilẹ̀ tí ẹ ti fọ́n ká sí.+ 35 Èmi yóò mú yín wá sínú aginjù àwọn èèyàn, màá sì dá yín lẹ́jọ́ níbẹ̀ ní ojúkojú.+
36 “‘Bí mo ṣe dá àwọn baba ńlá yín lẹ́jọ́ nínú aginjù ilẹ̀ Íjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe dá yín lẹ́jọ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 37 ‘Màá mú kí ẹ kọjá lábẹ́ ọ̀pá olùṣọ́ àgùntàn,+ màá sì mú kí ẹ tẹ̀ lé* májẹ̀mú náà. 38 Àmọ́ èmi yóò mú àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn tó ń ṣẹ̀ mí kúrò láàárín yín.+ Màá mú wọn kúrò ní ilẹ̀ àjèjì tí wọ́n wà, àmọ́ wọn ò ní wọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
39 “Ní tìrẹ, ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Kí kálukú yín lọ sin àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀.+ Àmọ́, tí ẹ kò bá fetí sí mi lẹ́yìn náà, ẹ ò ní lè fi àwọn ẹbọ yín àti àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ mi mọ́.’+
40 “‘Torí ní òkè mímọ́ mi, ní òkè gíga Ísírẹ́lì,+ ni gbogbo ilé Ísírẹ́lì yóò ti sìn mí ní ilẹ̀ náà, gbogbo wọn pátá,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.+ ‘Inú mi yóò dùn sí wọn níbẹ̀, èmi yóò sì béèrè ọrẹ yín àti àwọn àkọ́so ẹ̀bùn yín, gbogbo ohun mímọ́ yín.+ 41 Òórùn dídùn* náà yóò mú kí inú mi dùn sí yín, nígbà tí mo bá mú yín jáde láàárín àwọn èèyàn, tí mo sì kó yín jọ láti àwọn ilẹ̀ tí ẹ fọ́n ká sí;+ màá sì fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín yín níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè.’+
42 “‘Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ nígbà tí mo bá mú yín wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ sí ilẹ̀ tí mo búra pé màá fún àwọn baba ńlá yín. 43 Ibẹ̀ ni ẹ ó sì ti rántí gbogbo ìwà àti ìṣe yín tí ẹ fi sọ ara yín di aláìmọ́,+ ẹ ó sì kórìíra ara* yín nítorí gbogbo ohun búburú tí ẹ ṣe.+ 44 Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dojú ìjà kọ yín nítorí orúkọ mi,+ kì í ṣe nítorí ìwà búburú yín tàbí ìwà ìbàjẹ́ yín, ìwọ ilé Ísírẹ́lì,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
45 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 46 “Ọmọ èèyàn, yíjú sí gúúsù, kí o kéde ọ̀rọ̀ fún gúúsù, kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ fún igbó tó wà ní oko gúúsù. 47 Sọ fún igbó tó wà ní gúúsù pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò dáná sun ọ́,+ yóò sì jó gbogbo igi tútù àti gbogbo igi gbígbẹ inú rẹ run. Iná tó ń jó náà kò ní kú,+ yóò sì jó gbogbo ojú láti gúúsù dé àríwá. 48 Gbogbo ẹlẹ́ran ara* yóò wá rí i pé èmi Jèhófà, ló dáná sun ún, iná náà kò sì ní kú.”’”+
49 Mo sì sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ohun tí wọ́n ń sọ nípa mi ni pé, ‘Ṣebí àlọ́* lásán ló ń pa?’”
21 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, yíjú sí Jerúsálẹ́mù, kí o kéde ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ibi mímọ́, kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì. 3 Sọ fún ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Èmi yóò dojú ìjà kọ ọ́, màá fa idà mi yọ nínú àkọ̀,+ màá sì pa olódodo àti ẹni burúkú run láàárín rẹ. 4 Màá fa idà mi yọ nínú àkọ̀ láti bá gbogbo ẹlẹ́ran ara* jà láti gúúsù dé àríwá, torí pé mo fẹ́ pa olódodo àti ẹni burúkú run láàárín rẹ. 5 Gbogbo èèyàn á wá mọ̀ pé, èmi Jèhófà, ti fa idà mi yọ nínú àkọ̀. Kò sì ní pa dà síbẹ̀ mọ́.”’+
6 “Àti ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, mí kanlẹ̀ bí o* ṣe ń gbọ̀n, àní kí o mí kanlẹ̀ nínú ìbànújẹ́ níwájú wọn.+ 7 Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Kí ló dé tí o fi ń mí kanlẹ̀?’ kí o sọ pé, ‘Torí ìròyìn kan ni.’ Torí ó dájú pé ó máa dé, ìbẹ̀rù á sì mú kí gbogbo ọkàn domi, gbogbo ọwọ́ yóò rọ jọwọrọ, ìrẹ̀wẹ̀sì yóò bá gbogbo ẹ̀mí, omi á sì máa ro tótó ní gbogbo orúnkún.*+ ‘Wò ó! Ó dájú pé ó máa dé, ó máa ṣẹlẹ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
8 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 9 “Ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Sọ pé, ‘Idà!+ Wọ́n ti pọ́n idà, wọ́n sì ti dán an. 10 Wọ́n ti pọ́n ọn kó lè pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ; wọ́n ti dán an kó lè máa kọ mànà.’”’”
“Ṣebí ó yẹ ká yọ̀?”
“‘Ṣé ó* máa gé ọ̀pá àṣẹ ọmọ mi ni,+ bó ti ṣe sí gbogbo igi?
11 “‘A ti fi fúnni pé kí a dán an, kí a lè fi ọwọ́ jù ú fìrìfìrì. A ti pọ́n idà yìí, a sì ti dán an, kí a lè fún ẹni tó ń pààyàn.+
12 “‘Sunkún, kí o sì pohùn réré ẹkún,+ ọmọ èèyàn, torí ó ti dojú ìjà kọ àwọn èèyàn mi; ó dojú ìjà kọ gbogbo ìjòyè Ísírẹ́lì.+ Àwọn àti àwọn èèyàn mi ni idà náà máa pa. Torí náà, kí inú rẹ bà jẹ́, kí o sì lu itan rẹ. 13 Torí wọ́n ti yẹ̀ ẹ́ wò,+ kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ tí idà náà bá gé ọ̀pá àṣẹ náà? Kò* ní sí mọ́,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
14 “Ìwọ, ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o pàtẹ́wọ́, kí o sì sọ pé ‘Idà!’ lẹ́ẹ̀mẹta. Idà tó pa àwọn èèyàn, tó pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ ló yí wọn ká.+ 15 Ìbẹ̀rù yóò mú kí ọkàn wọn domi,+ ọ̀pọ̀ yóò sì ṣubú ní àwọn ẹnubodè ìlú wọn; èmi yóò fi idà pa wọ́n. Àní, ó ń kọ mànà, wọ́n sì ti dán an kó lè pa wọ́n! 16 Gé wọn féú féú lápá ọ̀tún! Bọ́ sí apá òsì! Lọ sí ibikíbi tí ojú rẹ bá lọ! 17 Èmi náà yóò pàtẹ́wọ́, màá sì bínú débi tó máa tẹ́ mi lọ́rùn.+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.”
18 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 19 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, la ọ̀nà méjì tí idà ọba Bábílónì yóò gbà wá. Ilẹ̀ kan náà ni méjèèjì yóò ti wá, kí o sì fi àmì* sí ibi tí ọ̀nà náà ti pínyà lọ sí ìlú méjèèjì. 20 La ọ̀nà kan tí idà náà máa gbà wọ Rábà+ ti àwọn ọmọ Ámónì láti bá a jà, kí ọ̀nà kejì sì wọ Jerúsálẹ́mù+ tí odi yí ká, ní Júdà. 21 Torí ọba Bábílónì dúró ní oríta náà, níbi tí ọ̀nà ti pín sí méjì, kó lè woṣẹ́. Ó mi àwọn ọfà. Ó wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà* rẹ̀; ó fi ẹ̀dọ̀ woṣẹ́. 22 Nígbà tó woṣẹ́, ohun tó rí ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ darí wọn sí Jerúsálẹ́mù, pé kí wọ́n gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri, kí wọ́n pàṣẹ láti pa ọ̀pọ̀, kí wọ́n kéde ogun, kí wọ́n gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri ti àwọn ẹnubodè, kí wọ́n mọ òkìtì yí i ká láti dó tì í, kí wọ́n sì fi iyẹ̀pẹ̀ mọ odi yí i ká.+ 23 Àmọ́, ó máa dà bí ìwoṣẹ́ irọ́ lójú àwọn* tó ti búra fún wọn.+ Ṣùgbọ́n ó rántí ẹ̀bi wọn, yóò sì mú wọn.+
24 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Ẹ ti mú kí a rántí ẹ̀bi yín bí ẹ ṣe ń fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín hàn, tí ẹ sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ yín hàn nínú gbogbo ìṣe yín. Ní báyìí tí a sì ti rántí yín, wọ́n á fi ipá* mú yín lọ.’
25 “Àmọ́ ọjọ́ rẹ ti dé, ìgbà tí o máa jìyà ìkẹyìn ti dé, ìwọ ìjòyè tí wọ́n ti ṣe léṣe, ìjòyè burúkú ti Ísírẹ́lì.+ 26 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Tú láwàní, kí o sì ṣí adé.+ Èyí ò ní rí bíi ti tẹ́lẹ̀.+ Gbé ẹni tó rẹlẹ̀ ga,+ kí o sì rẹ ẹni gíga wálẹ̀.+ 27 Àwókù, àwókù, ṣe ni màá sọ ọ́ di àwókù. Kò ní jẹ́ ti ẹnì kankan títí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin fi máa dé,+ òun sì ni èmi yóò fún.’+
28 “Ìwọ ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nípa àwọn ọmọ Ámónì àti nípa ẹ̀gàn wọn nìyí.’ Sọ pé, ‘Idà! Wọ́n ti fa idà yọ láti fi pa wọ́n; wọ́n ti dán an kó lè jẹ nǹkan run, kó sì lè máa kọ mànà. 29 Láìka ìran èké tí wọ́n rí àti iṣẹ́ irọ́ tí wọ́n wò nípa yín sí, wọ́n á kó yín jọ pelemọ sórí àwọn tí wọ́n pa,* àwọn èèyàn burúkú tí ọjọ́ wọn ti dé, ìgbà tí wọ́n máa jìyà ìkẹyìn. 30 Dá a pa dà sínú àkọ̀. Èmi yóò dá ọ lẹ́jọ́ níbi tí a ti ṣẹ̀dá rẹ, ní ilẹ̀ tí o ti wá. 31 Màá bínú sí ọ gidigidi. Ìbínú mi yóò jó ọ bí iná, màá sì mú kí ọwọ́ àwọn ìkà èèyàn tẹ̀ ọ́, àwọn tó mọ bí wọ́n ṣe ń pani run.+ 32 Wọ́n á fi ọ́ dáná;+ wọ́n á ta ẹ̀jẹ̀ rẹ sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà, wọn ò sì ní rántí rẹ mọ́, torí èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.’”
22 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, ṣé o ṣe tán láti kéde ìdájọ́ sórí* ìlú tó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀,+ ṣé o sì máa jẹ́ kó mọ gbogbo ohun ìríra tó ṣe?+ 3 Kí o sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ìwọ ìlú tí ò ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀+ nínú ara rẹ, tí àkókò rẹ ń bọ̀,+ tí ò ń ṣe àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* láti fi sọ ara rẹ di ẹlẹ́gbin,+ 4 ẹ̀jẹ̀ tí o ta sílẹ̀ ti mú kí o jẹ̀bi,+ àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ sì ti sọ ọ́ di aláìmọ́.+ O ti mú kí òpin àwọn ọjọ́ rẹ yára sún mọ́lé, àwọn ọdún rẹ sì ti dópin. Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kí àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀gàn rẹ, kí gbogbo ilẹ̀ sì fi ọ́ ṣẹlẹ́yà.+ 5 Àwọn ilẹ̀ tó wà nítòsí rẹ àti àwọn tó wà lọ́nà jíjìn yóò fi ọ́ ṣẹlẹ́yà,+ ìwọ tí orúkọ rẹ jẹ́ aláìmọ́, tí rúkèrúdò kún inú rẹ. 6 Wò ó! Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú yín ń lo agbára tó wà níkàáwọ́ wọn láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ 7 Inú rẹ ni wọ́n ti ń tàbùkù sí bàbá àti ìyá wọn.+ Wọ́n lu àjèjì ní jìbìtì, wọ́n sì ni ọmọ aláìníbaba* àti opó lára.”’”+
8 “‘Ẹ tàbùkù sí àwọn ibi mímọ́ mi, ẹ sì sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́.+ 9 Inú rẹ ni àwọn abanijẹ́ tó pinnu láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ wà.+ Wọ́n ń jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè nínú rẹ, wọ́n sì ń hùwà àìnítìjú láàárín rẹ.+ 10 Inú rẹ ni wọ́n ti tàbùkù sí ibùsùn bàbá wọn,*+ wọ́n sì bá obìnrin tó ń ṣe nǹkan oṣù lò pọ̀ nígbà tó ṣì jẹ́ aláìmọ́.+ 11 Inú rẹ ni ọkùnrin kan ti bá ìyàwó ọmọnìkejì rẹ̀ ṣe ohun ìríra,+ ẹlòmíì hùwà àìnítìjú ní ti pé ó bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ sùn, ẹlòmíì sì bá arábìnrin rẹ̀,+ tó jẹ́ ọmọ bàbá rẹ̀ lò pọ̀.+ 12 Inú rẹ ni wọ́n ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n lè ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ Ò ń yáni lówó èlé,+ ò ń jẹ èrè* lórí owó tí o yáni, o sì ń fipá gba owó lọ́wọ́ ọmọnìkejì rẹ.+ Àní, o ti gbàgbé mi pátápátá,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
13 “‘Wò ó! Mo pàtẹ́wọ́ tẹ̀gàntẹ̀gàn nítorí èrè tí kò tọ́ tí o jẹ àti nítorí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sílẹ̀ nínú rẹ. 14 Ṣé wàá ṣì ní ìgboyà,* ṣé ọwọ́ rẹ ṣì máa lágbára ní ọjọ́ tí mo bá fìyà jẹ ọ́?+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀, màá sì ṣe é. 15 Èmi yóò fọ́n ọ ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò tú ọ ká sí àwọn ilẹ̀,+ màá sì fòpin sí ìwà àìmọ́ rẹ.+ 16 Ìwọ kò ní níyì lójú àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”+
17 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 18 “Ọmọ èèyàn, ilé Ísírẹ́lì ti dà bí ìdàrọ́ tí kò wúlò lójú mi. Bàbà, tánganran, irin àti òjé tó wà nínú iná ìléru ni gbogbo wọn. Wọ́n ti di ìdàrọ́ fàdákà.+
19 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Torí pé gbogbo yín ti dà bí ìdàrọ́ tí kò wúlò,+ èmi yóò kó yín jọ sí Jerúsálẹ́mù. 20 Bí ìgbà tí wọ́n bá kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti tánganran jọ sínú iná ìléru, kí wọ́n lè koná mọ́ ọn kí wọ́n sì yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni màá fi ìbínú àti ìrunú kó yín jọ, màá koná mọ́ yín, màá sì yọ́ yín.+ 21 Èmi yóò kó yín jọ, èmi yóò koná ìbínú mi mọ́ yín,+ ẹ ó sì yọ́ nínú rẹ̀.+ 22 Bí fàdákà ṣe ń yọ́ nínú iná ìléru, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó ṣe yọ́ nínú rẹ̀; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti bínú sí yín gan-an.’”
23 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 24 “Ọmọ èèyàn, sọ fún un pé, ‘Ilẹ̀ tí wọn ò ní fọ̀ mọ́ ni ọ́, tí òjò kò sì ní rọ̀ sí ní ọjọ́ ìbínú. 25 Àwọn wòlíì rẹ̀ ti gbìmọ̀ pọ̀ ní àárín rẹ̀,+ bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù tó ń fa ẹran ya.+ Wọ́n ń jẹ àwọn èèyàn* run. Wọ́n ń fipá gba ìṣúra àti àwọn ohun iyebíye. Wọ́n ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di opó ní àárín rẹ̀. 26 Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti rú òfin mi,+ wọ́n sì ń sọ àwọn ibi mímọ́ mi di aláìmọ́.+ Wọn ò fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó mọ́ àti ohun yẹpẹrẹ,+ wọn ò jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tó mọ́,+ wọ́n sì kọ̀ láti pa àwọn sábáàtì mi mọ́, wọ́n sì ń pẹ̀gàn mi láàárín wọn. 27 Àwọn olórí tó wà láàárín rẹ̀ dà bí ìkookò tó ń fa ẹran ya; wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì ń pa àwọn èèyàn* láti jẹ èrè tí kò tọ́.+ 28 Àmọ́ àwọn wòlíì rẹ̀ ti fi ẹfun kun ohun tí wọ́n ṣe. Wọ́n ń rí ìran èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́,+ wọ́n sì ń sọ pé: “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí,” tó sì jẹ́ pé Jèhófà ò sọ̀rọ̀. 29 Àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ti lu jìbìtì, wọ́n sì ti jalè,+ wọ́n ti ni aláìní àti tálákà lára, wọ́n ti lu àjèjì ní jìbìtì, wọ́n sì ti fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú.’
30 “‘Mò ń wá ẹnì kan nínú wọn tí yóò tún ògiri olókùúta náà ṣe tàbí tó máa dúró níwájú mi síbi àlàfo náà torí ilẹ̀ náà, kó má bàa pa run,+ àmọ́ mi ò rí ẹnì kankan. 31 Torí náà, màá bínú sí wọn gidigidi, màá sì fi ìbínú mi tó ń jó bí iná pa wọ́n run. Màá fi ìwà wọn san wọ́n lẹ́san,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
23 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, àwọn obìnrin méjì kan wà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá kan náà.+ 3 Wọ́n di aṣẹ́wó ní Íjíbítì;+ láti kékeré ni wọ́n ti ń ṣe aṣẹ́wó. Wọ́n tẹ ọmú wọn níbẹ̀, wọ́n sì fọwọ́ pa wọ́n láyà nígbà tí wọn ò tíì mọ ọkùnrin. 4 Orúkọ ẹ̀gbọ́n ni Òhólà,* orúkọ àbúrò rẹ̀ sì ni Òhólíbà.* Wọ́n di tèmi, wọ́n sì bí àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin. Èyí tó ń jẹ́ Òhólà ni Samáríà,+ èyí tó sì ń jẹ́ Òhólíbà ni Jerúsálẹ́mù.
5 “Nígbà tí Òhólà ṣì jẹ́ tèmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣẹ́wó.+ Ọkàn rẹ̀ fà sí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àtàtà,+ àwọn ará Ásíríà tó jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ kó lè bá wọn ṣèṣekúṣe.+ 6 Gómìnà àti ìjòye ni wọ́n, wọ́n wọ aṣọ aláwọ̀ búlúù, gbogbo wọn jẹ́ géńdé tó dáa lọ́mọkùnrin, wọ́n ń gun ẹṣin. 7 Ó bá àwọn tó dáa jù lára àwọn ọmọkùnrin Ásíríà ṣèṣekúṣe, ó sì fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* tó jẹ́ ti àwọn tí ọkàn rẹ̀ ń fà sí sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin.+ 8 Kò jáwọ́ nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ṣe ní Íjíbítì, torí wọ́n ti bá a sùn nígbà èwe rẹ̀, wọ́n fọwọ́ pa á láyà nígbà tí kò tíì mọ ọkùnrin, wọ́n sì tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn lára rẹ̀.*+ 9 Torí náà, mo mú kí ọwọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àtàtà tẹ̀ ẹ́, àwọn ọmọ Ásíríà+ tí ọkàn rẹ̀ fà sí. 10 Wọ́n tú u sí ìhòòhò,+ wọ́n fi idà pa á, wọ́n sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin.+ Ìwà burúkú rẹ̀ mú kó gbajúmọ̀ láàárín àwọn obìnrin, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́.
11 “Nígbà tí Òhólíbà àbúrò rẹ̀ rí i, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn rẹ̀ tún burú sí i, ìṣekúṣe rẹ̀ sì wá burú jáì ju ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.+ 12 Ọkàn rẹ̀ fà sí àwọn ọmọkùnrin Ásíríà tí wọ́n wà nítòsí rẹ̀,+ gómìnà àti ìjòyè ni wọ́n, wọ́n wọ aṣọ iyì, wọ́n sì ń gun ẹṣin, gbogbo wọn jẹ́ géńdé tó dáa lọ́mọkùnrin. 13 Nígbà tó ba ara rẹ̀ jẹ́, mo rí i pé ọ̀nà kan náà ni àwọn méjèèjì tọ̀.+ 14 Àmọ́, ó túbọ̀ ń ṣèṣekúṣe. Ó rí ère àwọn ọkùnrin tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri, ère àwọn ará Kálídíà tí wọ́n kùn ní àwọ̀ pupa, 15 tí wọ́n de àmùrè mọ́ ìbàdí wọn, láwàní gígùn wà lórí wọn, wọ́n rí bíi jagunjagun, gbogbo wọn jọ àwọn ará Bábílónì, tí wọ́n bí ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà. 16 Bó ṣe rí wọn, ṣe ni ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí wọn láti bá wọn ṣèṣekúṣe, ó sì rán àwọn òjíṣẹ́ sí wọn ní Kálídíà.+ 17 Torí náà, àwọn ọmọ Bábílónì ń wá sórí ibùsùn tó ti ń ṣeré ìfẹ́, wọ́n sì fi ìṣekúṣe wọn sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin. Lẹ́yìn tí wọ́n sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin, ó* kórìíra wọn, ó sì fi wọ́n sílẹ̀.
18 “Nígbà tí kò fi iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ̀ bò mọ́, tó sì ń tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò,+ mo kórìíra rẹ̀, mo sì fi í sílẹ̀, bí mo ṣe kórìíra ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí mo* sì fi í sílẹ̀.+ 19 Ìṣekúṣe rẹ̀ sì ń pọ̀ sí i,+ ó ń rántí ìgbà èwe rẹ̀, tó ṣe aṣẹ́wó ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 20 Ọkàn rẹ̀ fà sí wọn bíi wáhàrì* àwọn ọkùnrin tí nǹkan ọkùnrin wọn dà bíi ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí ẹ̀yà ìbímọ wọn sì dà bíi ti ẹṣin. 21 Ó tún ń wù ọ́ láti máa hùwà àìnítìjú tí o hù ní Íjíbítì nígbà tí o wà léwe,+ tí wọ́n ń fọwọ́ pa ọ́ láyà, ìyẹn ọmú ìgbà èwe rẹ.+
22 “Torí náà, ìwọ Òhólíbà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò ru àwọn olólùfẹ́ rẹ sókè,+ àwọn tí o* kórìíra tí o sì fi sílẹ̀, èmi yóò sì mú kí wọ́n kọjú ìjà sí ọ láti ibi gbogbo,+ 23 àwọn ọmọkùnrin Bábílónì+ àti gbogbo ará Kálídíà,+ àwọn ará Pékódù,+ Ṣóà àti Kóà, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin Ásíríà. Géńdé tó dáa lọ́mọkùnrin ni gbogbo wọn, wọ́n jẹ́ gómìnà àti ìjòyè, jagunjagun àti àwọn tí wọ́n yàn,* gbogbo wọn ń gun ẹṣin. 24 Wọ́n á gbéjà kò ọ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àgbá kẹ̀kẹ́ rẹpẹtẹ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun, apata ńlá, asà* àti akoto.* Wọ́n á yí ọ ká, màá sì pàṣẹ pé kí wọ́n dá ọ lẹ́jọ́, wọ́n á sì ṣèdájọ́ rẹ bó ṣe tọ́ lójú wọn.+ 25 Èmi yóò bínú sí ọ, wọ́n á sì fi ìrunú bá ọ jà. Wọ́n á gé imú rẹ àti etí rẹ, idà ló sì máa pa àwọn tó bá ṣẹ́ kù nínú rẹ. Wọn yóò kó àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin lọ, iná sì máa run àwọn tó bá ṣẹ́ kù nínú rẹ.+ 26 Wọ́n á bọ́ aṣọ lára rẹ,+ wọ́n á sì gba ohun ọ̀ṣọ́ rẹ.+ 27 Èmi yóò fòpin sí ìwà àìnítìjú tí ò ń hù àti iṣẹ́ aṣẹ́wó+ tí o bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ O ò ní wò wọ́n mọ́, o ò sì ní rántí Íjíbítì mọ́.’
28 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Mo máa tó mú kí ọwọ́ àwọn tí o kórìíra tẹ̀ ọ́, àwọn tó rí ọ lára, tí o* sì fi sílẹ̀.+ 29 Ìkórìíra ni wọ́n á fi bá ọ jà, wọ́n á kó gbogbo ohun tí o ti ṣe làálàá fún lọ,+ wọ́n á sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò. Ìhòòhò rẹ tó ń tini lójú tí o fi ń ṣèṣekúṣe yóò hàn síta, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà àìnítìjú rẹ àti iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ.+ 30 Wọ́n á ṣe gbogbo nǹkan yìí sí ọ torí ò ń sáré tẹ̀ lé àwọn orílẹ̀-èdè bí aṣẹ́wó,+ torí o fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn sọ ara rẹ di ẹlẹ́gbin.+ 31 Ohun tí ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe ni ìwọ náà ń ṣe,+ màá sì fi ife rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.’+
32 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘Ìwọ yóò mu nínú ife ẹ̀gbọ́n rẹ, ife tí inú rẹ̀ jìn, tó sì fẹ̀.+
Wọ́n á fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n á sì fi ọ́ ṣẹlẹ́yà, èyí tó kún inú ife náà.+
33 Ìwọ yóò mu àmuyó, ìbànújẹ́ yóò sì bò ọ́,
Wàá mu látinú ife ìbẹ̀rù àti ti ahoro,
Ife Samáríà ẹ̀gbọ́n rẹ.
34 Ìwọ yóò mu nínú rẹ̀, ìwọ yóò mu ún gbẹ,+ wàá sì máa họ àpáàdì rẹ̀ jẹ,
Ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ ya.
“Torí èmi alára ti sọ̀rọ̀,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’
35 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Torí pé o ti gbàgbé mi, tí o sì ti pa mí tì pátápátá,*+ wàá jìyà ìwà àìnítìjú tí o hù àti iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ.’”
36 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé o máa kéde ìdájọ́ fún Òhólà àti Òhólíbà,+ kí o sì gbé ọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń ríni lára tí wọ́n ṣe kò wọ́n lójú? 37 Wọ́n ti ṣe àgbèrè,*+ ẹ̀jẹ̀ sì wà lọ́wọ́ wọn. Kì í ṣe pé wọ́n bá àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn ṣe àgbèrè nìkan ni, wọ́n tún sun àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún mi nínú iná kí wọ́n lè di oúnjẹ fún àwọn òrìṣà.+ 38 Ohun tí wọ́n tún ṣe nìyí: Wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di ẹlẹ́gbin ní ọjọ́ yẹn, wọ́n sì sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́. 39 Lẹ́yìn tí wọ́n pa àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n sì fi wọ́n rúbọ sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn,+ wọ́n wá sínú ibi mímọ́ mi kí wọ́n lè sọ ọ́ di aláìmọ́+ ní ọjọ́ yẹn gan-an. Ohun tí wọ́n ṣe nínú ilé mi nìyẹn. 40 Wọ́n tún rán ẹnì kan sí àwọn èèyàn kí wọ́n lè wá láti ọ̀nà jíjìn.+ Nígbà tí wọ́n ń bọ̀, o wẹ̀, o kun ojú rẹ, o sì fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ara rẹ lóge.+ 41 O jókòó sórí àga tìmùtìmù tó lọ́lá,+ wọ́n tẹ́ tábìlì síwájú àga náà,+ o sì gbé tùràrí mi + àti òróró mi sórí tábìlì náà.+ 42 Wọ́n gbọ́ ìró ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń jayé níbẹ̀, àwọn ọ̀mùtípara tí wọ́n mú wá láti aginjù wà lára wọn. Wọ́n fi ẹ̀gbà sọ́wọ́ àwọn obìnrin, wọ́n sì dé wọn ládé tó rẹwà.
43 “Mo wá sọ nípa obìnrin tí àgbèrè ti tán lókun pé: ‘Ní báyìí, kò ní jáwọ́ nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ń ṣe.’ 44 Wọ́n sì ń wọlé lọ bá a, bí ìgbà tí wọ́n ń lọ bá aṣẹ́wó. Bí wọ́n ṣe ń wọlé lọ bá Òhólà àti Òhólíbà nìyẹn, àwọn obìnrin tó ń hùwà àìnítìjú. 45 Àmọ́ ìdájọ́ tó tọ́ sí alágbèrè ni àwọn olódodo yóò ṣe fún un+ àti èyí tó tọ́ sí ẹni tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀;+ torí alágbèrè ni wọ́n, ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn.+
46 “Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Èmi yóò gbé àwọn ọmọ ogun dìde láti bá wọn jà, kí ìbẹ̀rù lè bò wọ́n, kí wọ́n sì kó wọn lẹ́rù.+ 47 Àwọn ọmọ ogun náà yóò sọ wọ́n ní òkúta,+ wọ́n á sì fi idà pa wọ́n. Wọ́n á pa àwọn ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin,+ wọ́n á sì dáná sun àwọn ilé wọn.+ 48 Èmi yóò fòpin sí ìwà àìnítìjú tí wọ́n ń hù ní ilẹ̀ náà, èyí á kọ́ gbogbo obìnrin lẹ́kọ̀ọ́, wọn ò sì ní hùwà àìnítìjú bíi tiyín.+ 49 Wọ́n á mú ẹ̀san ìwà àìnítìjú yín wá sórí yín àti ẹ̀san àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ dá pẹ̀lú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.’”+
24 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀ ní ọdún kẹsàn-án, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, kọ ọjọ́ òní* sílẹ̀, àní ọjọ́ òní yìí. Ọba Bábílónì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun ti Jerúsálẹ́mù lónìí yìí.+ 3 Pa òwe* nípa ọlọ̀tẹ̀ ilé náà, kí o sì sọ nípa wọn pé:
“‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Gbé ìkòkò oúnjẹ* kaná; gbé e sórí iná, kí o sì da omi sínú rẹ̀.+
4 Kó ẹran tí wọ́n gé sínú rẹ̀,+ gbogbo èyí tó dáa,
Itan àti èjìká; fi àwọn egungun tó dára jù kún inú rẹ̀.
5 Mú àgùntàn tó dára jù nínú agbo ẹran,+ kí o sì kó igi sábẹ́ ìkòkò náà yí ká.
Bọ ẹran náà, kí o sì se àwọn egungun náà nínú rẹ̀.”’
6 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘O gbé, ìwọ ìlú tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,+ ìkòkò oúnjẹ tó ti dípẹtà, tí wọn ò sì ha ìpẹtà rẹ̀ kúrò!
Kó o jáde ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan;+ má ṣe ṣẹ́ kèké lé wọn.
7 Torí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà nínú rẹ̀;+ ó dà á sórí àpáta lásán.
Kò dà á sórí ilẹ̀ kó lè fi iyẹ̀pẹ̀ bò ó.+
8 Kí ìbínú lè ru sókè láti gbẹ̀san,
Mo ti da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí àpáta tó ń dán,
Kí nǹkan má bàa bo ẹ̀jẹ̀ náà.’+
9 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí,
‘O gbé, ìwọ ìlú tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀!+
Èmi yóò to igi jọ pelemọ.
10 Kó igi náà jọ, kí o sì dáná sí i,
Bọ ẹran náà dáadáa, yọ́ omi rẹ̀, sì jẹ́ kí àwọn egungun rẹ̀ jóná.
11 Gbé ìkòkò náà ka ẹyin iná lófìfo kó lè gbóná,
Kí bàbà tí wọ́n fi ṣe é lè pọ́n yòò.
Ìdọ̀tí inú rẹ̀ yóò yọ́ kúrò,+ ìpẹtà rẹ̀ yóò sì jóná.
12 Ó ń dáni lágara, ó sì ń tánni lókun,
Torí ìpẹtà tó wà lára rẹ̀ kò ṣí kúrò.+
Jù ú sínú iná pẹ̀lú ìpẹtà rẹ̀!’
13 “‘Ìwà àìnítìjú rẹ ló mú kí o di aláìmọ́.+ Mo wẹ̀ ọ́ títí kí o lè mọ́, àmọ́ ìwà àìmọ́ rẹ kò kúrò. Ìwọ kì yóò mọ́ títí ìbínú mi sí ọ fi máa rọlẹ̀.+ 14 Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀. Yóò rí bẹ́ẹ̀. Ohun tí mo sọ ni màá ṣe, mi ò ní kẹ́dùn, mi ò sì ní pèrò dà.+ Wọ́n á fi ìwà àti ìṣe rẹ dá ọ lẹ́jọ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
15 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 16 “Ọmọ èèyàn, mo máa tó mú ẹni tí o fẹ́ràn kúrò lọ́dọ̀ rẹ lójijì.+ Má ṣe ṣọ̀fọ̀;* má ṣe sunkún, má sì da omi lójú. 17 Banú jẹ́, àmọ́ má ṣe jẹ́ kó hàn síta, má tẹ̀ lé àṣà àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ òkú.+ Wé láwàní rẹ,+ kí o sì wọ bàtà rẹ.+ Má bo ẹnu* rẹ,+ má sì jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlòmíì bá gbé wá fún ọ.”*+
18 Àárọ̀ ni mo bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀, ìyàwó mi sì kú ní alẹ́. Torí náà, nígbà tí ilẹ̀ mọ́, mo ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún mi. 19 Àwọn èèyàn náà ń sọ fún mi pé: “Ṣé o ò ní sọ fún wa bí àwọn ohun tí ò ń ṣe yìí ṣe kàn wá?” 20 Mo fún wọn lésì pé: “Jèhófà ti bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, 21 ‘Sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé: “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Mo máa tó sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ ibi pàtàkì tí ẹ fi ń yangàn, tí ẹ fẹ́ràn gidigidi, tó sì máa ń wù yín.* Idà ni wọn yóò fi pa àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin tí ẹ fi sílẹ̀.+ 22 Ẹ ó sì wá ṣe bí mo ti ṣe. Ẹ ò ní bo ẹnu yín, ẹ ò sì ní jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlòmíì bá gbé wá fún yín.+ 23 Láwàní yín yóò wà lórí yín, bàtà yín yóò sì wà ní ẹsẹ̀ yín. Ẹ ò ní ṣọ̀fọ̀, ẹ ò sì ní sunkún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ ó rọ dà nù nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín,+ ẹ ó sì banú jẹ́ láàárín ara yín. 24 Ìsíkíẹ́lì ti di àmì fún yín.+ Ohun tó ṣe ni ẹ̀yin náà yóò ṣe. Nígbà tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ ó wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.’”’”
25 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, ní ọjọ́ tí mo bá mú ibi ààbò wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn, ohun tó rẹwà tó ń fún wọn láyọ̀, tí wọ́n fẹ́ràn gidigidi, tó sì máa ń wù wọ́n,* pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin,+ 26 ẹni tó bá sá àsálà yóò wá ròyìn rẹ̀ fún ọ.+ 27 Ní ọjọ́ yẹn, ìwọ yóò la ẹnu rẹ, wàá bá ẹni tó sá àsálà sọ̀rọ̀, o ò sì ní ya odi mọ́.+ Ìwọ yóò di àmì fún wọn, wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”
25 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, yíjú sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí wọn.+ 3 Kí o sọ nípa àwọn ọmọ Ámónì pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Torí ẹ sọ pé ‘Àháà!’ nígbà tí wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, nígbà tí wọ́n sọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì di ahoro àti nígbà tí ilé Júdà lọ sí ìgbèkùn, 4 torí náà, èmi yóò mú kí ọwọ́ àwọn ará Ìlà Oòrùn tẹ̀ ọ́, wàá sì di ohun ìní wọn. Wọ́n á kọ́ àwọn ibùdó* wọn sínú rẹ, wọ́n á sì pàgọ́ wọn sáàárín rẹ. Wọ́n á jẹ èso rẹ, wọ́n á sì mu wàrà rẹ. 5 Èmi yóò sọ Rábà+ di ibi tí àwọn ràkúnmí á ti máa jẹko, èmi yóò sì sọ ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì di ibi ìsinmi agbo ẹran; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”
6 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Torí ẹ pàtẹ́wọ́,+ tí ẹ fẹsẹ̀ kilẹ̀, tí ẹ* sì ń yọ̀ bí ẹ ṣe ń fi ilẹ̀ Ísírẹ́lì ṣe irú ẹlẹ́yà yìí,+ 7 torí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ yín, kí n lè mú kí àwọn orílẹ̀-èdè kó ẹrù yín lọ. Màá pa yín rẹ́ láàárín àwọn èèyàn, màá sì pa yín run ní àwọn ilẹ̀ náà.+ Màá pa yín rẹ́, ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
8 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí Móábù+ àti Séírì + sọ pé: “Wò ó! Ilé Júdà dà bíi gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù,” 9 èmi yóò mú kó rọrùn láti gbógun ti àwọn ìlú tó wà ní ẹ̀gbẹ́* Móábù, ní ààlà rẹ̀. Àwọn ló rẹwà* jù ní ilẹ̀ náà, Bẹti-jẹ́ṣímótì, Baali-méónì, títí dé Kiriátáímù.+ 10 Màá mú kí ọwọ́ àwọn ará Ìlà Oòrùn+ tẹ òun àti àwọn ọmọ Ámónì, yóò sì di ohun ìní wọn, kí a má bàa rántí àwọn ọmọ Ámónì mọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 11 Èmi yóò ṣèdájọ́ ní Móábù,+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
12 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Édómù ti gbẹ̀san lára ilé Júdà, wọ́n sì ti jẹ̀bi gidigidi torí ẹ̀san tí wọ́n gbà;+ 13 torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá tún na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ Édómù, èmi yóò pa àwọn èèyàn àti ẹran ọ̀sìn ibẹ̀, èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro.+ Idà ni yóò pa wọ́n láti Témánì títí dé Dédánì.+ 14 ‘Màá lo àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì láti gbẹ̀san lára Édómù.+ Wọ́n á mú ìbínú mi àti ìrunú mi wá sórí Édómù, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ló ń gbẹ̀san lára wọn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’
15 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èrò ìkà tó wà lọ́kàn àwọn Filísínì* ti mú kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe gbẹ̀san kí wọ́n sì pani run, torí wọn ò yéé kórìíra.+ 16 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ àwọn Filísínì,+ màá pa àwọn Kérétì rẹ́,+ màá sì run àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn tó ń gbé ní etí òkun.+ 17 Màá gbẹ̀san lára wọn lọ́nà tó lé kenkà, màá fi ìbínú jẹ wọ́n níyà, wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá gbẹ̀san lára wọn.”’”
26 Ní ọdún kọkànlá, ní ọjọ́ kìíní oṣù, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, torí pé Tírè ti sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé,+ ‘Àháà! Wọ́n ti fọ́ ilẹ̀kùn àwọn èèyàn náà!+ Gbogbo nǹkan á di tèmi, màá sì wá di ọlọ́rọ̀ torí ó ti di ahoro báyìí’; 3 torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Màá bá ọ jà, ìwọ Tírè, màá sì gbé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè dìde sí ọ, bí òkun ṣe ń gbé ìgbì rẹ̀ dìde. 4 Wọ́n á run ògiri Tírè, wọ́n á wó àwọn ilé gogoro rẹ̀,+ màá ha iyẹ̀pẹ̀ rẹ̀ kúrò, màá sì sọ ọ́ di àpáta lásán tó ń dán. 5 Yóò di ibi tí wọ́n ń sá àwọ̀n sí láàárín òkun.’+
“‘Torí èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kó o ní ẹrù. 6 Idà ni yóò pa àwọn agbègbè* tó wà ní ìgbèríko rẹ̀ run, àwọn èèyàn á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
7 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò mú kí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì gbéjà ko Tírè láti àríwá;+ ọba àwọn ọba ni,+ pẹ̀lú àwọn ẹṣin,+ kẹ̀kẹ́ ogun,+ àwọn tó ń gẹṣin àti ọ̀pọ̀ ọmọ ogun.* 8 Yóò fi idà pa àwọn agbègbè tó wà ní ìgbèríko rẹ run, yóò mọ odi láti gbéjà kò ọ́, yóò mọ òkìtì láti dó tì ọ́, yóò sì fi apata ńlá bá ọ jà. 9 Yóò fi igi* tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri kọ lu ògiri rẹ, yóò sì fi àáké* wó àwọn ilé gogoro rẹ. 10 Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò pọ̀ débi pé wọ́n á fi eruku bò ọ́, ìró àwọn tó ń gẹṣin, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ àti kẹ̀kẹ́ ogun yóò mú kí àwọn ògiri rẹ mì tìtì nígbà tó bá gba àwọn ẹnubodè rẹ wọlé, bí ìgbà táwọn èèyàn ń rọ́ wọ ìlú tí ògiri rẹ̀ ti wó. 11 Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò fi pátákò wọn tẹ gbogbo ojú ọ̀nà rẹ mọ́lẹ̀;+ yóò fi idà pa àwọn èèyàn rẹ, àwọn òpó ńláńlá rẹ yóò sì wó lulẹ̀. 12 Wọ́n á kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ, wọ́n á kó àwọn ọjà rẹ bí ẹrù ogun,+ wọ́n á ya àwọn ògiri rẹ lulẹ̀, wọ́n á wó àwọn ilé rẹ tó rẹwà; wọ́n á wá da àwọn òkúta rẹ, àwọn iṣẹ́ tí o fi igi ṣe àti iyẹ̀pẹ̀ rẹ sínú omi.’
13 “‘Màá fòpin sí ariwo orin yín, wọn ò sì ní gbọ́ ìró àwọn háàpù rẹ mọ́.+ 14 Màá sọ ọ́ di àpáta lásán tó ń dán àti ibi tí wọ́n ti ń sá àwọ̀n.+ Wọn ò ní tún ọ kọ́ láé, torí èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
15 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún Tírè nìyí: ‘Tí ìró ìṣubú rẹ bá dún, tí àwọn tó ń kú lọ* ń kérora, tí wọ́n pa ọ̀pọ̀ láàárín rẹ, ǹjẹ́ àwọn erékùṣù ò ní mì jìgìjìgì?+ 16 Gbogbo àwọn olórí* òkun yóò sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí ìtẹ́ wọn, wọ́n á bọ́ aṣọ* wọn, títí kan èyí tí wọ́n kó iṣẹ́ sí, jìnnìjìnnì á sì bò wọ́n.* Wọ́n á jókòó sílẹ̀, wọ́n á máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, wọ́n á sì máa wò ọ́ tìyanutìyanu.+ 17 Wọ́n á kọ orin arò*+ torí rẹ, wọ́n á sì sọ fún ọ pé:
“Wo bí o ti ṣègbé,+ ìwọ tí àwọn tó wá láti òkun ń gbé inú rẹ̀, ìwọ ìlú tí wọ́n ń yìn;
Ìwọ àti àwọn* tó ń gbé inú rẹ jẹ́ alágbára lórí òkun,+
Ẹ sì ń dẹ́rù ba gbogbo àwọn tó ń gbé ayé!
18 Àwọn erékùṣù yóò gbọ̀n rìrì ní ọjọ́ tí o bá ṣubú,
Ìdààmú yóò bá àwọn erékùṣù òkun ní ọjọ́ tí o bá lọ.”’+
19 “Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ahoro, bí àwọn ìlú tí ẹnikẹ́ni kò gbé inú rẹ̀, nígbà tí mo bá mú kí omi ya lù ọ́, tí omi tó ń ru gùdù sì bò ọ́ mọ́lẹ̀,+ 20 màá mú ìwọ àti àwọn tó ń bá ọ lọ sínú kòtò* lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹni àtijọ́; màá sì mú kí o máa gbé níbi tó rẹlẹ̀ jù lọ, bí àwọn ibi àtijọ́ tó ti di ahoro, pẹ̀lú àwọn tó ń lọ sínú kòtò,+ kí ẹnì kankan má bàa gbé inú rẹ. Màá sì wá ṣe ilẹ̀ alààyè lógo.*
21 “‘Màá mú kí jìnnìjìnnì bá ọ lójijì, ìwọ kò sì ní sí mọ́.+ Wọ́n á wá ọ àmọ́ wọn ò ní rí ọ mọ́ láé,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
27 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, kọ orin arò* nípa Tírè,+ 3 kí o sì sọ fún Tírè pé,
‘Ìwọ tí ń gbé ní àwọn ẹnu ọ̀nà òkun,
Ò ń bá àwọn èèyàn láti ọ̀pọ̀ erékùṣù dòwò pọ̀,
Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Ìwọ Tírè, o ti sọ pé, ‘Ẹwà mi ò lábùlà.’+
4 Àárín òkun ni àwọn ilẹ̀ rẹ wà,
Àwọn tó kọ́ ọ ti mú kí o rẹwà gan-an.
5 Igi júnípà ti Sénírì+ ni wọ́n fi ṣe gbogbo pákó rẹ,
Wọ́n sì fi igi kédárì láti Lẹ́bánónì ṣe òpó inú ọkọ̀ rẹ.
6 Àwọn igi ràgàjì* ti Báṣánì ni wọ́n fi ṣe àwọn àjẹ̀ rẹ,
Igi sípírẹ́sì tí wọ́n fi eyín erin tẹ́ inú rẹ̀ láti àwọn erékùṣù Kítímù+ ni wọ́n fi ṣe iwájú ọkọ̀ rẹ.
7 Aṣọ ọ̀gbọ̀* aláràbarà láti Íjíbítì ni wọ́n fi ṣe ìgbòkun rẹ,
Fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti òwú aláwọ̀ pọ́pù láti erékùṣù Élíṣáhì+ ni wọ́n fi ṣe ìbòrí ọkọ̀ rẹ.
8 Àwọn tó ń gbé Sídónì àti Áfádì+ ló ń bá ọ tukọ̀.
Ìwọ Tírè, àwọn èèyàn rẹ tó já fáfá ló ń bá ọ tukọ̀.+
9 Àwọn ará Gébálì+ tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́* tí wọ́n sì já fáfá ló dí àwọn àlàfo ara ọkọ̀ rẹ.+
Gbogbo ọkọ̀ òkun àti àwọn atukọ̀ wọn wá bá ọ dòwò pọ̀.
10 Àwọn ará Páṣíà, Lúdì àti Pútì+ wà lára àwọn jagunjagun rẹ, àwọn ọkùnrin ogun rẹ.
Inú rẹ ni wọ́n gbé apata àti akoto* wọn kọ́ sí, wọ́n sì ṣe ọ́ lógo.
11 Àwọn ará Áfádì tó wà lára àwọn ọmọ ogun rẹ wà lórí ògiri rẹ yí ká,
Àwọn ọkùnrin onígboyà sì wà nínú àwọn ilé gogoro rẹ.
Wọ́n gbé àwọn apata* wọn kọ́ sára ògiri rẹ yí ká,
Wọ́n sì buyì kún ẹwà rẹ.
12 “‘“Táṣíṣì+ bá ọ dòwò pọ̀ torí ọrọ̀ rẹ pọ̀ rẹpẹtẹ.+ Fàdákà, irin, tánganran àti òjé ni wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.+ 13 Jáfánì, Túbálì+ àti Méṣékì+ bá ọ dòwò pọ̀, wọ́n sì fi àwọn ohun tí wọ́n fi bàbà ṣe àti àwọn ẹrú+ ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ. 14 Ilé Tógámà+ fi ẹṣin àti àwọn ẹṣin ogun àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ. 15 Àwọn ará Dédánì+ bá ọ dòwò pọ̀; o gba àwọn oníṣòwò síṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ erékùṣù; eyín erin+ àti igi ẹ́bónì ni wọ́n fi san ìṣákọ́lẹ̀* fún ọ. 16 Édómù bá ọ dòwò pọ̀ torí ọjà rẹ pọ̀ gan-an. Òkúta tọ́kọ́wásì, òwú aláwọ̀ pọ́pù, aṣọ tí wọ́n kóṣẹ́ aláràbarà sí, aṣọ àtàtà, iyùn àti òkúta rúbì ni wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.
17 “‘“Júdà àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì bá ọ dòwò pọ̀, wọ́n ń fi àlìkámà* Mínítì,+ àwọn oúnjẹ tó dára jù, oyin,+ òróró àti básámù+ ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.+
18 “‘“Damásíkù+ bá ọ dòwò pọ̀ torí ọjà rẹ pọ̀ rẹpẹtẹ àti torí gbogbo ọrọ̀ rẹ, ó fi wáìnì Hélíbónì àti irun àgùntàn Séhárì* bá ọ ṣòwò. 19 Fédánì àti Jáfánì láti Úsálì fi àwọn ohun tí wọ́n fi irin ṣe, igi kaṣíà* àti pòròpórò* ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ. 20 Dédánì + fi aṣọ tí wọ́n ń tẹ́ sẹ́yìn ẹran* ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ. 21 O gba àwọn Árábù àti gbogbo ìjòyè Kídárì+ síṣẹ́, àwọn tó ń fi ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́ ṣòwò.+ 22 Àwọn oníṣòwò Ṣébà àti Ráámà+ bá ọ dòwò pọ̀; wọ́n fi onírúurú lọ́fínńdà tó dáa jù, àwọn òkúta iyebíye àti wúrà ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.+ 23 Háránì,+ Kánè àti Édẹ́nì,+ àwọn oníṣòwò Ṣébà,+ Áṣúrì+ àti Kílímádì bá ọ dòwò pọ̀. 24 Ní àwọn ọjà rẹ, wọ́n ń ta àwọn aṣọ tó rẹwà, àwọn ìborùn búlúù tí wọ́n kóṣẹ́ aláràbarà sí àti àwọn kápẹ́ẹ̀tì aláràbarà. Wọ́n kó gbogbo wọn jọ, wọ́n sì fi okùn dè wọ́n.
25 Àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+ lo fi kó àwọn ọjà rẹ,
Débi pé ọjà kún inú rẹ, o sì kún fọ́fọ́* láàárín òkun.
26 Àwọn atukọ̀ rẹ ti wà ọ́ wá sínú agbami òkun;
Atẹ́gùn ìlà oòrùn ti mú kí o fọ́ sáàárín òkun.
27 Ọrọ̀ rẹ, àwọn ọjà rẹ, àwọn nǹkan tí ò ń tà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ rẹ àti àwọn atukọ̀ rẹ,
Àwọn tó ń dí àwọn àlàfo ara ọkọ̀ rẹ, àwọn tó ń bá ọ ṣòwò+ àti àwọn jagunjagun,+
Gbogbo àwọn* tó wà pẹ̀lú rẹ,
Gbogbo wọn ni yóò rì sínú òkun ní ọjọ́ tí o bá ṣubú.+
28 Gbogbo èbúté yóò mì tìtì nígbà tí àwọn atukọ̀ rẹ bá figbe ta.
29 Gbogbo àwọn tó ń fi àjẹ̀ tukọ̀, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ àti àwọn atukọ̀
Yóò kúrò nínú ọkọ̀ wọn, wọ́n á sì dúró sórí ilẹ̀.
30 Wọ́n á gbé ohùn wọn sókè, wọ́n á sì sunkún kíkan nítorí rẹ+
Bí wọ́n ṣe ń da eruku sórí ara wọn, tí wọ́n sì ń yíra nínú eérú.
31 Wọ́n á fá irun orí wọn, wọ́n á sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀;*
Wọ́n á sunkún kíkan* torí rẹ, wọ́n á sì pohùn réré ẹkún gidigidi.
32 Bí wọ́n bá ń dárò, wọn yóò máa kọrin arò nípa rẹ pé:
‘Ta ló dà bíi Tírè, tó ti dákẹ́ sínú òkun?+
33 Nígbà tí àwọn ọjà rẹ ti òkun dé, o tẹ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́rùn.+
Ọrọ̀ rẹ tó pọ̀ rẹpẹtẹ àti àwọn ọjà rẹ ti sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.+
34 O ti wá dákẹ́ sínú agbami òkun, sínú ibú omi,+
Ìwọ àti gbogbo ọjà rẹ àti àwọn èèyàn rẹ ti rì sínú òkun.+
35 Gbogbo àwọn tó ń gbé ní àwọn erékùṣù yóò wò ọ́ tìyanutìyanu,+
Ìbẹ̀rù yóò mú kí jìnnìjìnnì bá àwọn ọba wọn,+ ìdààmú yóò sì hàn lójú wọn.
36 Àwọn oníṣòwò tó wà láwọn orílẹ̀-èdè yóò súfèé torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ.
Ìparun rẹ yóò dé lójijì, yóò sì burú jáì,
O ò sì ní sí mọ́ títí láé.’”’”+
28 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ fún aṣáájú Tírè pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Torí pé ò ń gbéra ga nínú ọkàn rẹ,+ tí o sì ń sọ pé, ‘ọlọ́run ni mí.
Orí ìtẹ́ ọlọ́run ni mo jókòó sí láàárín òkun.’+
Àmọ́ èèyàn lásán ni ọ́, o kì í ṣe ọlọ́run,
Bí o tiẹ̀ ń pe ara rẹ ní ọlọ́run nínú ọkàn rẹ.
3 Wò ó! O gbọ́n ju Dáníẹ́lì lọ.+
Kò sí àṣírí tó pa mọ́ fún ọ.
4 O ti fi ọgbọ́n àti òye rẹ sọ ara rẹ di ọlọ́rọ̀,
O sì ń kó wúrà àti fàdákà jọ síbi ìṣúra rẹ.+
5 Bí o ṣe já fáfá nídìí òwò rẹ ti mú kí ọrọ̀ rẹ pọ̀ rẹpẹtẹ,+
O sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga nínú ọkàn rẹ nítorí ọrọ̀ rẹ.”’
6 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Torí ò ń pe ara rẹ ní ọlọ́run nínú ọkàn rẹ,
7 Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì wá bá ọ jà, àwọn tó burú jù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+
Wọn yóò fa idà yọ sí gbogbo ohun tó rẹwà tí o fi ọgbọ́n rẹ kó jọ,
Wọn yóò sì sọ ògo rẹ tó rẹwà di aláìmọ́.+
9 Ṣé wàá ṣì sọ fún ẹni tó fẹ́ pa ọ́ pé, ‘ọlọ́run ni mí?’
Èèyàn lásán lo máa jẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń sọ ọ́ di aláìmọ́, o ò ní jẹ́ ọlọ́run.”’
10 ‘Ìwọ yóò kú lọ́wọ́ àwọn àjèjì bí aláìdádọ̀dọ́,*
Torí èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
11 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀ pé: 12 “Ọmọ èèyàn, kọ orin arò* nípa ọba Tírè, kí o sì sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
13 O wà ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run.
Gbogbo òkúta iyebíye ni mo fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́,
Rúbì, tópásì àti jásípérì; kírísóláítì, ónísì àti jéèdì; sàfáyà, tọ́kọ́wásì+ àti émírádì;
Wúrà sì ni mo fi ṣe ojú ibi tí wọ́n lẹ̀ wọ́n mọ́.
Ọjọ́ tí mo dá ọ ni mo ṣe wọ́n.
14 Mo fi ọ́ ṣe kérúbù aláàbò tí mo fòróró yàn.
O wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run,+ o sì rìn kiri láàárín àwọn òkúta oníná.
Torí náà, màá ta ọ́ nù kúrò ní òkè Ọlọ́run bí ẹni tí wọ́n kẹ́gàn, màá sì pa ọ́ run,+
Ìwọ kérúbù aláàbò, màá pa ọ́ run kúrò láàárín àwọn òkúta oníná.
17 O bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga nínú ọkàn rẹ torí ẹwà rẹ.+
Ògo rẹ tó rẹwà mú kí o ba ọgbọ́n rẹ jẹ́.+
Èmi yóò jù ọ́ sí ilẹ̀.+
Màá sì mú kí àwọn ọba fi ọ́ ṣe ìran wò.
18 O ti sọ àwọn ibi mímọ́ rẹ di aláìmọ́ nítorí pé ẹ̀bi rẹ pọ̀, o ò sì ṣòótọ́ nídìí òwò rẹ.
Màá mú kí iná sọ láàárín rẹ, yóò sì jẹ ọ́ run.+
Màá sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀ lójú gbogbo àwọn tó ń wò ọ́.
19 Gbogbo àwọn tó mọ̀ ọ́ láàárín àwọn èèyàn yóò wò ọ́ tìyanutìyanu.+
Ìparun rẹ yóò dé lójijì, yóò sì burú jáì,
O ò sì ní sí mọ́ títí láé.”’”+
20 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 21 “Ọmọ èèyàn, yíjú rẹ sọ́dọ̀ Sídónì,+ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí rẹ̀. 22 Kí o sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Màá bá ọ jà, ìwọ Sídónì, wọ́n á sì yìn mí lógo láàárín rẹ;
Àwọn èèyàn á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dá a lẹ́jọ́, tí mo sì fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ nínú rẹ̀.
23 Màá fi àjàkálẹ̀ àrùn kọ lù ú, ẹ̀jẹ̀ á sì ṣàn ní àwọn ojú ọ̀nà rẹ̀.
Àwọn tí wọ́n pa yóò ṣubú láàárín rẹ̀ nígbà tí idà bá dojú kọ ọ́ láti ibi gbogbo;
Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+
24 “‘“Ẹ̀gún tó ń ṣeni léṣe àti òṣùṣú tó ń roni lára kò ní yí ilé Ísírẹ́lì ká mọ́,+ àwọn ló ń fi ilé Ísírẹ́lì ṣe ẹlẹ́yà; àwọn èèyàn á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”’
25 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Nígbà tí mo bá tún kó ilé Ísírẹ́lì jọ láti àárín àwọn èèyàn tí wọ́n fọ́n ká sí,+ màá fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín wọn lójú àwọn orílẹ̀-èdè.+ Wọ́n á sì máa gbé lórí ilẹ̀ wọn+ tí mo fún Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi.+ 26 Wọn yóò máa gbé ibẹ̀, ààbò yóò sì wà lórí wọn,+ wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà,+ nígbà tí mo bá ṣèdájọ́ gbogbo àwọn tó yí wọn ká tó ń fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,+ ààbò yóò wà lórí wọn; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn.”’”
29 Ní ọdún kẹwàá, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kejìlá, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀ pé: 2 “Ọmọ èèyàn, yíjú sọ́dọ̀ Fáráò ọba Íjíbítì, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí rẹ̀ àti sórí gbogbo Íjíbítì.+ 3 Sọ pé: ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Èmi yóò bá ọ jà, ìwọ Fáráò ọba Íjíbítì,+
Ẹran ńlá inú àwọn odò Náílì* rẹ̀,+
Tó sọ pé, ‘Èmi ni mo ni odò Náílì mi.
Ara mi ni mo ṣe é fún.’+
4 Àmọ́ èmi yóò fi ìwọ̀ kọ́ ẹnu rẹ, màá sì mú kí ẹja inú odò Náílì rẹ lẹ̀ mọ́ àwọn ìpẹ́ rẹ.
Èmi yóò mú ọ jáde láti inú odò Náílì rẹ pẹ̀lú gbogbo ẹja inú odò Náílì tó lẹ̀ mọ́ àwọn ìpẹ́ rẹ.
5 Èmi yóò pa ọ́ tì sínú aṣálẹ̀, ìwọ àti gbogbo ẹja odò Náílì rẹ.
Orí pápá gbalasa ni wàá ṣubú sí, wọn ò ní kó ọ jọ, wọn ò sì ní ṣà ọ́ jọ.+
Màá fi ọ́ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko orí ilẹ̀ àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.+
6 Gbogbo àwọn tó ń gbé Íjíbítì á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,
Torí wọn ò lè ti ilé Ísírẹ́lì lẹ́yìn mọ́, wọn ò yàtọ̀ sí pòròpórò* lásán.+
7 Ìwọ fọ́ nígbà tí wọ́n dì ọ́ lọ́wọ́ mú,
O sì mú kí èjìká wọn ya.
8 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá fi idà bá ọ jà,+ màá sì pa èèyàn àti ẹranko inú rẹ run. 9 Ilẹ̀ Íjíbítì yóò pa run, yóò sì di ahoro;+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, torí o ti sọ pé,* ‘Èmi ni mo ni odò Náílì; èmi ni mo ṣe é.’+ 10 Torí náà, màá bá ìwọ àti odò Náílì rẹ jà, màá mú kí ilẹ̀ Íjíbítì dá páropáro kó sì gbẹ, yóò di ahoro,+ láti Mígídólì+ dé Síénè,+ títí dé ààlà Etiópíà. 11 Èèyàn tàbí ẹran ọ̀sìn kankan kò ní fi ẹsẹ̀ rin ibẹ̀ kọjá,+ ẹnikẹ́ni ò sì ní gbé ibẹ̀ fún ogójì (40) ọdún. 12 Èmi yóò mú kí ilẹ̀ Íjíbítì di ahoro ju àwọn ilẹ̀ yòókù lọ, àwọn ìlú rẹ̀ yóò sì ṣófo ju àwọn ìlú yòókù lọ fún ogójì (40) ọdún;+ màá tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, màá sì fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀.”+
13 “‘Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Lẹ́yìn ogójì (40) ọdún, èmi yóò pa dà kó àwọn ará Íjíbítì jọ láti àárín àwọn èèyàn tí wọ́n tú ká sí;+ 14 Èmi yóò mú àwọn ẹrú Íjíbítì pa dà wá sí ilẹ̀ Pátírọ́sì,+ ilẹ̀ tí wọ́n ti wá, wọ́n á sì di ìjọba tí kò já mọ́ nǹkan kan níbẹ̀. 15 Íjíbítì yóò rẹlẹ̀ ju àwọn ìjọba yòókù lọ, kò ní jọba lé àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́,+ màá sì mú kí wọ́n kéré débi pé wọn ò ní lè tẹ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lórí ba.+ 16 Ilé Ísírẹ́lì ò tún ní gbára lé Íjíbítì mọ́,+ àmọ́ ṣe ló máa rán wọn létí pé wọ́n ṣàṣìṣe nígbà tí wọ́n ní kí àwọn ará Íjíbítì ran àwọn lọ́wọ́. Wọn yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”’”
17 Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kìíní, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 18 “Ọmọ èèyàn, Nebukadinésárì*+ ọba Bábílónì mú kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣiṣẹ́ kára láti gbógun ti Tírè.+ Gbogbo orí wọn pá, gbogbo èjìká wọn sì bó. Àmọ́ òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò gba owó iṣẹ́ kankan fún gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lórí Tírè.
19 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Èmi yóò fún Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ yóò kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ, yóò sì kó ọ̀pọ̀ ẹrù rẹ̀, yóò kó o bọ̀ láti ogun; ìyẹn yóò sì jẹ́ èrè fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀.’
20 “‘Torí iṣẹ́ tó ṣe fún mi, èmi yóò fún un ní ilẹ̀ Íjíbítì láti fi ṣe èrè iṣẹ́ àṣekára tó ṣe láti gbógun tì í,’*+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
21 “Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò mú kí ìwo kan hù jáde fún ilé Ísírẹ́lì,*+ èmi yóò sì fún ọ láǹfààní láti sọ̀rọ̀ láàárín wọn; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”
30 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Ẹ pohùn réré ẹkún, kí ẹ sì sọ pé, ‘Áà, ọjọ́ náà ń bọ̀!’
3 Torí ọjọ́ náà sún mọ́lé, àní ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé.+
Ọjọ́ ìkùukùu* ni yóò jẹ́,+ àkókò ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+
4 Idà yóò dojú kọ Íjíbítì, ìbẹ̀rù á sì bo Etiópíà nígbà tí òkú bá sùn ní Íjíbítì;
Wọ́n ti kó ọrọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti wó ìpìlẹ̀ rẹ̀.+
5 Etiópíà,+ Pútì,+ Lúdì àti onírúurú èèyàn náà*
Àti Kúbù, pẹ̀lú àwọn ọmọ ilẹ̀ májẹ̀mú,*
Idà ni yóò pa gbogbo wọn.”’
6 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
‘Àwọn tó ń ti Íjíbítì lẹ́yìn pẹ̀lú yóò ṣubú,
Agbára tó ń mú kó gbéra ga yóò sì wálẹ̀.’+
“‘Idà ni yóò pa wọ́n ní ilẹ̀ náà, láti Mígídólì+ dé Síénè,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 7 ‘Wọ́n á di ahoro ju àwọn ilẹ̀ yòókù lọ, àwọn ìlú rẹ̀ á sì di ahoro ju àwọn ìlú yòókù lọ.+ 8 Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dá iná sí Íjíbítì, tí mo sì tẹ gbogbo àwọn tó bá a ṣàdéhùn rẹ́. 9 Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò rán àwọn òjíṣẹ́ nínú àwọn ọkọ̀ òkun, kí wọ́n lè mú kí Etiópíà tó dá ara rẹ̀ lójú gbọ̀n rìrì; ẹ̀rù yóò bà wọ́n ní ọjọ́ ìdájọ́ tó ń bọ̀ wá sórí Íjíbítì, torí ó dájú pé ó máa dé.’
10 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò mú kí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ará Íjíbítì run.+ 11 Òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn tó burú jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè+ yóò wá láti pa ilẹ̀ náà run. Wọ́n á fa idà wọn yọ láti bá Íjíbítì jà, wọ́n á sì fi òkú àwọn tí wọ́n pa kún ilẹ̀ náà.+ 12 Èmi yóò sọ àwọn omi tó ń ṣàn láti odò Náílì+ di ilẹ̀ gbígbẹ, èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn èèyàn burúkú. Màá mú kí àwọn àjèjì sọ ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ di ahoro.+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.’
13 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò tún pa àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* run, màá sì pa àwọn ọlọ́run Nófì*+ tí kò ní láárí run. Kò ní sí ọmọ Íjíbítì tó máa ṣe olórí* mọ́, màá sì mú kí ìbẹ̀rù wà ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 14 Màá pa Pátírọ́sì+ run, màá dá iná sí Sóánì, màá sì dá Nóò* lẹ́jọ́.+ 15 Màá bínú sí Sínì, ibi ààbò Íjíbítì, màá sì pa àwọn ará Nóò run. 16 Màá dá iná sí Íjíbítì; ìbẹ̀rù á bo Sínì, wọ́n á ya wọ Nóò, wọ́n á sì gbógun ti Nófì* ní ojúmọmọ! 17 Idà ni yóò pa àwọn géńdé ọkùnrin Ónì* àti Píbésétì, wọ́n á sì kó àwọn ìlú náà lọ sí oko ẹrú. 18 Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tehafínéhésì nígbà tí mo bá ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà Íjíbítì níbẹ̀.+ Agbára tó ń mú kó gbéra ga yóò dópin,+ ìkùukùu* á bò ó, àwọn ìlú rẹ̀ yóò sì lọ sí oko ẹrú.+ 19 Èmi yóò dá Íjíbítì lẹ́jọ́, wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”
20 Ní ọdún kọkànlá, ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ keje, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 21 “Ọmọ èèyàn, mo ti kán apá Fáráò ọba Íjíbítì; wọn ò ní dì í kó lè jinná tàbí kí wọ́n fi aṣọ wé e kó lè lágbára tó láti di idà mú.”
22 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò kọjú ìjà sí Fáráò ọba Íjíbítì,+ màá sì kán apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tó ti kán tẹ́lẹ̀ àtèyí tí kò tíì kán,+ màá sì mú kí idà já bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.+ 23 Màá wá tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, màá sì fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀.+ 24 Èmi yóò fún ọwọ́ ọba Bábílónì lágbára,*+ màá sì fi idà mi sí i lọ́wọ́.+ Èmi yóò ṣẹ́ apá Fáráò, yóò sì kérora gidigidi bí ẹni tó ń kú lọ níwájú rẹ̀.* 25 Èmi yóò fún ọwọ́ ọba Bábílónì lágbára, àmọ́ ọwọ́ Fáráò yóò rọ; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá fi idà mi sọ́wọ́ ọba Bábílónì, tó sì fì í, kó lè bá ilẹ̀ Íjíbítì jà.+ 26 Màá sì tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, màá fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀,+ wọn yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”
31 Ní ọdún kọkànlá, ní oṣù kẹta, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ fún Fáráò ọba Íjíbítì àti ọ̀pọ̀ èèyàn rẹ̀ pé,+
‘Ta ló lágbára bíi tìrẹ?
3 Ará Ásíríà kan wà, igi kédárì ní Lẹ́bánónì,
Tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ rẹwà, tó ṣíji bolẹ̀, tó sì ga fíofío;
Orí rẹ̀ kan àwọsánmà.*
4 Omi mú kó di ńlá, àwọn ìsun omi sì mú kó ga.
Omi tó ń ṣàn wà yí ká ibi tí wọ́n gbìn ín sí;
Àwọn ipadò rẹ̀ bomi rin gbogbo igi inú oko.
5 Ìdí nìyẹn tó fi ga ju gbogbo igi yòókù lọ nínú oko.
Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i, ọwọ́ rẹ̀ sì ń gùn
Torí omi pọ̀ nínú àwọn odò rẹ̀.
6 Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run kọ́ ìtẹ́ wọn sí ara àwọn ẹ̀ka rẹ̀,
Gbogbo ẹranko bímọ sí abẹ́ àwọn ẹ̀ka rẹ̀,
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ńláńlá sì ń gbé abẹ́ ibòji rẹ̀.
7 Ẹwà rẹ̀ ga lọ́lá, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn dáadáa,
Torí pé àwọn gbòǹgbò rẹ̀ wọnú omi tó pọ̀.
8 Kò sí igi kédárì kankan nínú ọgbà Ọlọ́run+ tó ṣeé fi wé e.
Kò sí igi júnípà kankan tí ẹ̀ka rẹ̀ dà bíi tirẹ̀,
Kò sì sí àwọn igi alára dídán* tí ẹ̀ka wọn dà bíi tirẹ̀.
Kò sí igi míì nínú ọgbà Ọlọ́run tó lẹ́wà bíi tirẹ̀.
9 Mo mú kó rẹwà, kí ewé rẹ̀ sì pọ̀ rẹpẹtẹ,
Gbogbo igi yòókù tó wà ní Édẹ́nì, nínú ọgbà Ọlọ́run tòótọ́ sì ń jowú rẹ̀.’
10 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí pé ó* ga gan-an, tí orí rẹ̀ kan àwọsánmà,* tó sì ń gbéra ga nínú ọkàn rẹ̀ torí pé ó ga, 11 èmi yóò fi í lé alágbára tó ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́.+ Ó dájú pé ó máa bá a jà, èmi yóò sì kọ̀ ọ́ torí ìwà ìkà rẹ̀. 12 Àwọn àjèjì, àwọn tó burú jù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò gé e lulẹ̀, wọ́n á sì pa á tì sórí àwọn òkè, àwọn ewé rẹ̀ á já bọ́ sí gbogbo àfonífojì, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ á sì ṣẹ́ sínú gbogbo odò ilẹ̀ náà.+ Gbogbo èèyàn ayé yóò kúrò lábẹ́ ibòji rẹ̀, wọ́n á sì pa á tì. 13 Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run á máa gbé lórí ìtì rẹ̀ tó wó lulẹ̀, gbogbo ẹran inú igbó á sì máa gbé lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀.+ 14 Èyí máa rí bẹ́ẹ̀, kó má bàa sí igi kankan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tó máa ga tó bẹ́ẹ̀, tí orí rẹ̀ á kan àwọsánmà,* kí igi kankan tó ń rí omi mu dáadáa má sì ga tó wọn. Torí gbogbo wọn ló máa kú, wọ́n á lọ sí ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọmọ aráyé tí wọ́n ń lọ sínú kòtò.’*
15 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ní ọjọ́ tó bá lọ sínú Isà Òkú,* màá mú kí wọ́n ṣọ̀fọ̀. Torí náà, èmi yóò bo ibú omi, màá sì sé àwọn odò rẹ̀ kí omi tó pọ̀ náà má bàa ṣàn. Màá mú kí Lẹ́bánónì ṣókùnkùn torí rẹ̀, gbogbo igi oko yóò sì gbẹ dà nù. 16 Tí ìró ìṣubú rẹ̀ bá dún, màá mú kí àwọn orílẹ̀-èdè gbọ̀n rìrì nígbà tí mo bá mú un lọ sí Isà Òkú* pẹ̀lú gbogbo àwọn tó ń lọ sínú kòtò* àti gbogbo igi Édẹ́nì,+ èyí tó dáa jù tó sì jẹ́ ààyò ti Lẹ́bánónì, gbogbo àwọn tó ń rí omi mu dáadáa, yóò rí ìtùnú ní ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀. 17 Wọ́n ti bá a lọ sínú Isà Òkú,* sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fi idà pa,+ pẹ̀lú àwọn tó ń tì í lẹ́yìn,* tí wọ́n ń gbé lábẹ́ òjìji rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.’+
18 “‘Igi wo ní Édẹ́nì ló ní ògo tó sì lágbára bíi tìrẹ?+ Àmọ́, ó dájú pé ìwọ àti àwọn igi Édẹ́nì yóò lọ sínú ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀. Àárín àwọn aláìdádọ̀dọ́* ni wàá dùbúlẹ̀ sí, pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fi idà pa. Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Fáráò àti gbogbo èèyàn rẹ̀ nìyí,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
32 Ní ọdún kejìlá, ní oṣù kejìlá, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, kọ orin arò* nípa Fáráò ọba Íjíbítì, kí o sì sọ fún un pé,
‘O dà bí ọmọ kìnnìún tó lágbára* ní àwọn orílẹ̀-èdè,
Àmọ́ wọ́n ti pa ọ́ lẹ́nu mọ́.
O dà bí ẹran ńlá inú òkun,+ ò ń jà gùdù nínú odò rẹ,
Ò ń fi ẹsẹ̀ rẹ da omi rú, o sì ń dọ̀tí àwọn odò.’*
3 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘Màá da àwọ̀n mi bò ọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó kóra jọ,
Wọ́n á sì fi àwọ̀n mi wọ́ ọ síta.
4 Èmi yóò pa ọ́ tì sórí ilẹ̀;
Màá jù ọ́ sórí pápá gbalasa.
Màá mú kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé ọ,
Màá sì fi ọ́ bọ́ àwọn ẹran inú igbó ní gbogbo ayé.+
5 Èmi yóò ju ẹran rẹ sórí àwọn òkè,
Màá sì fi ara rẹ tó ṣẹ́ kù kún inú àwọn àfonífojì.+
6 Màá fi ẹ̀jẹ̀ rẹ tó ń tú jáde rin ilẹ̀ náà títí dé orí àwọn òkè,
Yóò sì kún inú àwọn odò.’*
7 ‘Tí òpin bá sì ti dé bá ọ, èmi yóò bo ojú ọ̀run, màá sì mú kí àwọn ìràwọ̀ wọn ṣókùnkùn.
8 Èmi yóò mú kí gbogbo orísun ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run ṣókùnkùn torí rẹ,
Èmi yóò sì mú kí òkùnkùn bo ilẹ̀ rẹ,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
9 ‘Èmi yóò mú kí ìdààmú bá ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tí mo bá mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè míì,
Lọ sí àwọn ilẹ̀ tí o kò mọ̀.+
10 Èmi yóò mú kí ẹnu ya ọ̀pọ̀ èèyàn,
Ìbẹ̀rù á sì mú kí àwọn ọba wọn gbọ̀n rìrì torí rẹ nígbà tí mo bá fi idà mi níwájú wọn.
Kálukú wọn á máa gbọ̀n jìnnìjìnnì, torí ẹ̀mí ara rẹ̀,
Ní ọjọ́ tí o bá ṣubú.’
11 Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘Idà ọba Bábílónì yóò wá sórí rẹ.+
12 Èmi yóò mú kí idà àwọn jagunjagun tó lákíkanjú pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn rẹ,
Àwọn tó burú jù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn.+
Wọ́n á rẹ ìgbéraga Íjíbítì wálẹ̀, wọ́n á sì run gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ.+
13 Màá pa gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi rẹ̀ tó pọ̀ run,+
Ẹsẹ̀ èèyàn tàbí pátákò ẹran ọ̀sìn kankan kò sì ní dà wọ́n rú mọ́.’+
14 ‘Ní àkókò yẹn, èmi yóò mú kí omi wọn tòrò,
Màá sì mú kí odò wọn ṣàn bí òróró’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
15 ‘Nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ Íjíbítì di ahoro, tí wọ́n kó gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ lọ,+
Nígbà tí mo bá pa gbogbo àwọn tó ń gbé inú rẹ̀,
Wọ́n á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+
16 Orin arò nìyí, ó sì dájú pé àwọn èèyàn máa kọ ọ́;
Àwọn ọmọbìnrin àwọn orílẹ̀-èdè máa kọ ọ́.
Wọ́n á kọ ọ́ nítorí Íjíbítì àti nítorí gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
17 Ní ọdún kejìlá, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 18 “Ọmọ èèyàn, pohùn réré ẹkún torí àwọn ará Íjíbítì tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ, kí o sì mú un lọ sí ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀, òun àti àwọn ọmọbìnrin àwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára, pẹ̀lú àwọn tó ń lọ sínú kòtò.*
19 “‘Ta ni ìwọ fi ẹwà rẹ jù lọ? Lọ sísàlẹ̀, kí o lọ dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìdádọ̀dọ́!’*
20 “‘Wọ́n á ṣubú sí àárín àwọn tí wọ́n fi idà pa.+ Wọ́n ti fà á lé idà lọ́wọ́; ẹ wọ́ ọ lọ, pẹ̀lú gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ.
21 “‘Láti inú Isà Òkú* ni àwọn jagunjagun tó lákíkanjú jù lọ yóò ti bá òun àti àwọn tó ń ràn án lọ́wọ́ sọ̀rọ̀. Ó dájú pé wọ́n á lọ sí ìsàlẹ̀, wọ́n á sì dùbúlẹ̀ bí àwọn aláìdádọ̀dọ́* tí wọ́n fi idà pa. 22 Ásíríà àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ wà níbẹ̀. Sàréè wọn yí i ká, gbogbo wọn ni wọ́n fi idà pa.+ 23 Ìsàlẹ̀ kòtò* ni àwọn sàréè rẹ̀ wà, àwọn èèyàn rẹ̀ sì yí sàréè rẹ̀ ká, gbogbo wọn ni wọ́n fi idà pa, torí wọ́n dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè.
24 “‘Élámù+ àti gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ wà níbẹ̀ tí wọ́n yí sàréè rẹ̀ ká, gbogbo wọn ni wọ́n fi idà pa. Wọ́n ti lọ sí ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀ láìdádọ̀dọ́,* àwọn tí wọ́n dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè. Ojú á wá tì wọ́n pẹ̀lú àwọn tó ń lọ sínú kòtò.* 25 Wọ́n ti ṣe ibùsùn fún un láàárín àwọn tí wọ́n pa, tòun ti gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ tó yí sàréè rẹ̀ ká. Aláìdádọ̀dọ́* ni gbogbo wọn, tí wọ́n fi idà pa, torí wọ́n ń dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè; ojú á sì tì wọ́n pẹ̀lú àwọn tó ń lọ sínú kòtò.* Àárín àwọn tí wọ́n pa ni wọ́n gbé e sí.
26 “‘Ibẹ̀ ni Méṣékì àti Túbálì+ àti gbogbo èèyàn wọn* tó pọ̀ rẹpẹtẹ wà. Sàréè wọn* yí i ká. Aláìdádọ̀dọ́* ni gbogbo wọn, wọ́n fi idà gún wọn pa, torí wọ́n dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè. 27 Ṣé wọn ò ní dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn jagunjagun tó lákíkanjú tí kò dádọ̀dọ́,* tí wọ́n ti ṣubú, tí wọ́n sì lọ sínú Isà Òkú* pẹ̀lú àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń jagun? Wọ́n á fi idà wọn sábẹ́ orí wọn,* wọ́n á sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wọn sórí egungun wọn, torí pé àwọn jagunjagun tó lákíkanjú yìí dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè. 28 Àmọ́ ní tìrẹ, wọn yóò tẹ̀ ọ́ rẹ́ láàárín àwọn aláìdádọ̀dọ́,* ìwọ yóò sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fi idà pa.
29 “‘Édómù+ wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọba rẹ̀ àti gbogbo ìjòyè rẹ̀, àwọn tó jẹ́ pé, láìka bí wọ́n ṣe lágbára sí, wọ́n dùbúlẹ̀ sáàárín àwọn tí wọ́n fi idà pa; àwọn náà yóò dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìdádọ̀dọ́*+ àti àwọn tó ń lọ sínú kòtò.*
30 “‘Gbogbo àwọn ìjòyè* àríwá wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ará Sídónì,+ tí wọ́n fi ìtìjú lọ sísàlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n pa, láìka bí wọ́n ṣe fi agbára wọn dẹ́rù bani sí. Wọn yóò dùbúlẹ̀ láìdádọ̀dọ́* pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fi idà pa, ojú á sì tì wọ́n pẹ̀lú àwọn tó ń lọ sínú kòtò.*
31 “‘Fáráò yóò rí gbogbo nǹkan yìí, gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn rẹ̀ yóò sì tù ú nínú;+ wọn yóò fi idà pa Fáráò àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
32 “‘Torí pé ó dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè, Fáráò àti àwọn èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ yóò lọ sinmi pẹ̀lú àwọn aláìdádọ̀dọ́,* pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fi idà pa,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
33 Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, bá àwọn ọmọ èèyàn rẹ sọ̀rọ̀,+ kí o sì sọ fún wọn pé,
“‘Ká sọ pé mo mú idà wá sórí ilẹ̀ kan,+ tí gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà mú ọkùnrin kan, tí wọ́n sì fi ṣe olùṣọ́ wọn, 3 tó sì rí idà tó ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ náà, tó fun ìwo, tó sì kìlọ̀ fún àwọn èèyàn.+ 4 Tí ẹnì kan bá gbọ́ tí ìwo dún àmọ́ tí kò fetí sí ìkìlọ̀,+ tí idà wá, tó sì gba ẹ̀mí rẹ̀,* ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní ọrùn òun fúnra rẹ̀.+ 5 Ó gbọ́ tí ìwo dún, àmọ́ kò gba ìkìlọ̀. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní ọrùn rẹ̀. Ká ní ó gba ìkìlọ̀ ni, ì bá gba ẹ̀mí* ara rẹ̀ là.
6 “‘Àmọ́ tí olùṣọ́ náà bá rí i pé idà ń bọ̀, tí kò fun ìwo,+ tí àwọn èèyàn kò sì rí ìkìlọ̀ gbà, tí idà sì dé, tó sì gba ẹ̀mí* ẹnì kan nínú wọn, ẹni yẹn á kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, àmọ́ màá béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́ náà.’*+
7 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Ísírẹ́lì, nígbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, kí o bá mi kìlọ̀ fún wọn.+ 8 Tí mo bá sọ fún ẹni burúkú pé, ‘Ìwọ ẹni burúkú, ó dájú pé wàá kú!’+ àmọ́ tí ìwọ kò sọ ohunkóhun láti kìlọ̀ fún ẹni burúkú náà pé kó yí ìwà rẹ̀ pa dà, ẹni burúkú náà yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,+ àmọ́ ọwọ́ rẹ ni màá ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 9 Àmọ́ tí o bá kìlọ̀ fún ẹni burúkú pé kó yí ìwà rẹ̀ pa dà tí kò sì yí pa dà, ẹni burúkú náà yóò kú torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ó dájú pé ìwọ yóò gba ẹ̀mí* rẹ là.+
10 “Ìwọ ọmọ èèyàn, sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘O ti sọ pé: “Ọ̀tẹ̀ wa àti ẹ̀ṣẹ̀ wa ti dẹ́rù pa wá, ó ń mú kó rẹ̀ wá;+ báwo la ṣe máa wá wà láàyè?”’+ 11 Sọ fún wọn pé, ‘“Bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, “inú mi ò dùn sí ikú ẹni burúkú,+ bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí ìwà rẹ̀ pa dà,+ kó sì máa wà láàyè.+ Ẹ yí pa dà, ẹ yí ìwà búburú yín pa dà,+ ṣé ó wá yẹ kí ẹ kú ni, ilé Ísírẹ́lì?”’+
12 “Ìwọ ọmọ èèyàn, sọ fún àwọn ọmọ èèyàn rẹ pé, ‘Bí olódodo bá ṣọ̀tẹ̀, òdodo rẹ̀ kò ní gbà á là;+ bẹ́ẹ̀ sì ni ìwà burúkú ẹni burúkú kò ní mú kó kọsẹ̀ nígbà tó bá fi ìwà búburú rẹ̀ sílẹ̀;+ olódodo kò sì ní lè máa wà láàyè nítorí òdodo rẹ̀ lọ́jọ́ tó bá dẹ́ṣẹ̀.+ 13 Tí mo bá sọ fún olódodo pé: “Ó dájú pé ìwọ yóò máa wà láàyè,” tó wá gbẹ́kẹ̀ lé òdodo rẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa,*+ mi ò ní rántí ìkankan nínú iṣẹ́ òdodo rẹ̀, àmọ́ yóò kú torí ohun tí kò dáa tó ṣe.+
14 “‘Tí mo bá sì sọ fún ẹni burúkú pé: “Ó dájú pé wàá kú,” tó wá fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó jẹ́ òdodo,+ 15 tí ẹni burúkú náà wá dá ohun tí wọ́n fi ṣe ìdúró pa dà,+ tó dá àwọn nǹkan tó jí pa dà,+ tó ń hùwà tó dáa láti fi hàn pé òun ń tẹ̀ lé àṣẹ tó ń fúnni ní ìyè, ó dájú pé yóò máa wà láàyè.+ Kò ní kú. 16 Èmi kò ní ka èyíkéyìí nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sí i lọ́rùn.*+ Ó dájú pé yóò máa wà láàyè torí ó ṣe ohun tó tọ́, ó sì ṣe òdodo.’+
17 “Àmọ́ àwọn èèyàn rẹ sọ pé, ‘Ọ̀nà Jèhófà kò tọ́,’ nígbà tó jẹ́ pé ọ̀nà tiwọn ni kò tọ́.
18 “Tí olódodo bá fi òdodo tó ń ṣe sílẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa, yóò kú nítorí ìwà rẹ̀.+ 19 Àmọ́ tí ẹni burúkú bá yí pa dà kúrò nínú iṣẹ́ ibi rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó jẹ́ òdodo, yóò máa wà láàyè torí ohun tó ṣe.+
20 “Àmọ́ ẹ ti sọ pé, ‘Ọ̀nà Jèhófà kò tọ́.’+ Èmi yóò fi ìwà kálukú dá a lẹ́jọ́, ìwọ ilé Ísírẹ́lì.”
21 Nígbà tó yá, ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹwàá, ọdún kejìlá tí a ti wà ní ìgbèkùn, ọkùnrin kan tó sá àsálà kúrò ní Jerúsálẹ́mù wá bá mi,+ ó sì sọ pé: “Wọ́n ti pa ìlú náà run!”+
22 Àmọ́ ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí ọkùnrin tó sá àsálà náà wá, ọwọ́ Jèhófà wá sára mi, ó sì ti la ẹnu mi kí ọkùnrin náà tó wá bá mi ní àárọ̀. Ẹnu mi wá là, mi ò sì yadi mọ́.+
23 Ni Jèhófà bá bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 24 “Ọmọ èèyàn, àwọn tó ń gbé ibi àwókù yìí+ ń sọ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹnì kan péré ni Ábúráhámù, síbẹ̀ ó gba ilẹ̀ náà.+ Àmọ́ àwa pọ̀; ó dájú pé wọ́n ti fún wa ní ilẹ̀ náà kó lè di ohun ìní wa.’
25 “Torí náà, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ tòun ti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ ẹ̀ ń gbé ojú yín sókè sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* yín, ẹ sì ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ Ẹ sì wá rò pé ilẹ̀ náà máa di tiyín? 26 Ẹ ti gbẹ́kẹ̀ lé idà yín,+ ẹ̀ ń ṣe ohun tó ń ríni lára, kálukú yín sì ti bá ìyàwó ọmọnìkejì rẹ̀ sùn.+ Ẹ sì wá rò pé ilẹ̀ náà máa di tiyín?”’+
27 “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún wọn ni pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Bí mo ti wà láàyè, wọ́n á fi idà pa àwọn tó ń gbé inú àwókù náà; èmi yóò sọ àwọn tó wà lórí pápá gbalasa di oúnjẹ fún àwọn ẹranko; àrùn yóò sì pa àwọn tó wà nínú ibi ààbò àti ihò inú àwọn àpáta.+ 28 Èmi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro pátápátá,+ òpin á sì dé bá ìgbéraga rẹ̀, àwọn òkè Ísírẹ́lì yóò di ahoro,+ ẹnikẹ́ni ò sì ní gba ibẹ̀ kọjá. 29 Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, nígbà tí mo bá mú kí ilẹ̀ náà di ahoro pátápátá,+ nítorí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ṣe.”’+
30 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, àwọn èèyàn rẹ ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ògiri àti ní ẹnu ọ̀nà àwọn ilé.+ Wọ́n ń sọ fún ara wọn, kálukú ń sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.’ 31 Wọn yóò rọ́ wá bá ọ, kí wọ́n lè jókòó síwájú rẹ bí èèyàn mi; wọ́n á sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àmọ́ wọn ò ní ṣe ohun tí wọ́n gbọ́.+ Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ dídùn fún ọ,* àmọ́ bí wọ́n ṣe máa jèrè tí kò tọ́ ló wà lọ́kàn wọn. 32 Wò ó! Lójú wọn, o dà bí orin ìfẹ́, tí wọ́n fi ohùn dídùn kọ, tí wọ́n sì fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọ lọ́nà tó já fáfá. Wọ́n á gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àmọ́ wọn ò ní tẹ̀ lé e. 33 Ó máa ṣẹ, tó bá ti wá ṣẹ, wọ́n á wá mọ̀ pé wòlíì kan ti wà láàárín wọn.”+
34 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì. Sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ gbé, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì,+ tí ẹ̀ ń bọ́ ara yín! Ǹjẹ́ kì í ṣe agbo ẹran ló yẹ kí ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn máa bọ́?+ 3 Ẹ̀ ń jẹ ọ̀rá, ẹ̀ ń wọ aṣọ tí wọ́n fi irun àgùntàn ṣe, ẹ sì ń pa àwọn ẹran tó sanra jù lọ,+ àmọ́ ẹ ò bọ́ agbo ẹran.+ 4 Ẹ ò tọ́jú èyí tó rẹ̀ kó lè lágbára, ẹ ò tọ́jú èyí tó ń ṣàìsàn kí ara rẹ̀ lè yá, ẹ ò fi aṣọ wé èyí tó fara pa, ẹ ò lọ mú àwọn tó rìn lọ pa dà wálé, ẹ ò sì wá èyí tó sọ nù;+ kàkà bẹ́ẹ̀, ọwọ́ líle ni ẹ fi ń dà wọ́n, ẹ sì hùwà ìkà sí wọn.+ 5 Wọ́n wá fọ́n ká torí kò sí olùṣọ́ àgùntàn;+ wọ́n fọ́n ká, wọ́n sì di oúnjẹ fún gbogbo ẹran inú igbó. 6 Àwọn àgùntàn mi ń rìn kiri lórí gbogbo òkè ńlá àti lórí gbogbo òkè kéékèèké; àwọn àgùntàn mi fọ́n ká sí gbogbo ayé, kò sì sí ẹni tó ń wá wọn kiri tàbí tó ń béèrè ibi tí wọ́n wà.
7 “‘“Torí náà, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: 8 ‘“Bí mo ti ń bẹ láàyè,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, “torí pé àwọn àgùntàn mi ti di ẹran tí wọ́n fẹ́ pa, tí wọ́n sì ti di oúnjẹ fún gbogbo ẹran inú igbó, torí pé kò sí olùṣọ́ àgùntàn kankan, tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn mi kò sì wá àwọn àgùntàn mi; àmọ́ tí wọ́n ń bọ́ ara wọn, tí wọn ò sì bọ́ àwọn àgùntàn mi,”’ 9 torí náà, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. 10 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò bá àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà jà, màá mú kí wọ́n jíhìn ohun tí wọ́n ṣe sí àwọn àgùntàn mi,* mi ò ní jẹ́ kí wọ́n bọ́* àwọn àgùntàn mi mọ́,+ àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà kò sì ní bọ́ ara wọn mọ́. Màá gba àwọn àgùntàn mi sílẹ̀ ní ẹnu wọn, wọn ò sì ní rí wọn jẹ mọ́.’”
11 “‘Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Wò ó, èmi fúnra mi yóò wá àwọn àgùntàn mi, màá sì bójú tó wọn.+ 12 Èmi yóò bójú tó àwọn àgùntàn mi bí olùṣọ́ àgùntàn tó rí àwọn àgùntàn rẹ̀ tó fọ́n ká, tó sì ń fún wọn ní oúnjẹ.+ Èmi yóò gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò ní gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ní ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà.+ 13 Èmi yóò mú wọn jáde láàárín àwọn èèyàn, màá sì kó wọn jọ láti àwọn ilẹ̀. Èmi yóò mú wọn wá sórí ilẹ̀ wọn, màá sì bọ́ wọn lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tó ń ṣàn àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé ní ilẹ̀ náà. 14 Èmi yóò bọ́ wọn ní ibi ìjẹko tó dáa, ilẹ̀ tí wọ́n á sì ti máa jẹko yóò wà lórí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì.+ Wọ́n á dùbúlẹ̀ síbẹ̀, níbi ìjẹko tó dáa,+ orí ilẹ̀ tó sì dáa jù lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì ni wọ́n á ti máa jẹ ewéko.”
15 “‘“Èmi fúnra mi yóò bọ́ àwọn àgùntàn mi,+ èmi fúnra mi yóò sì mú kí wọ́n dùbúlẹ̀,”+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 16 “Màá wá èyí tó sọ nù,+ màá mú èyí tó rìn lọ pa dà wálé, màá fi aṣọ wé èyí tó fara pa, màá sì tọ́jú èyí tó rẹ̀ kó lè lágbára; àmọ́ èmi yóò pa èyí tó sanra àti èyí tó lágbára. Èmi yóò dá a lẹ́jọ́.”
17 “‘Ní tiyín, ẹ̀yin àgùntàn mi, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Mo máa tó ṣèdájọ́ láàárín àgùntàn kan àti àgùntàn mìíràn, láàárín àwọn àgbò àti àwọn òbúkọ.+ 18 Ṣé bí ẹ ṣe ń jẹ̀ ní ibi ìjẹko tó dáa jù kò tó yín? Ṣé ó tún yẹ kí ẹ fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn ewéko yòókù mọ́lẹ̀ ní ibi ìjẹko yín? Lẹ́yìn tí ẹ sì ti mu omi tó mọ́ jù, ṣé ó wá yẹ kí ẹ fi ẹsẹ̀ yín da omi náà rú? 19 Ṣé kí àwọn àgùntàn mi wá máa jẹ ewéko tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọ́n sì máa mu omi tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ dà rú?”
20 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún wọn nìyí: “Wò ó, èmi fúnra mi yóò ṣèdájọ́ láàárín àgùntàn tó sanra àti èyí tó rù, 21 torí ẹ̀ ń fi ẹ̀gbẹ́ àti èjìká yín tì wọ́n, ẹ sì ń fi ìwo yín kan gbogbo àwọn tó ń ṣàìsàn, títí ẹ fi tú wọn káàkiri. 22 Èmi yóò gba àwọn àgùntàn mi là, wọn ò sì ní dọdẹ wọn mọ́;+ èmi yóò sì ṣèdájọ́ láàárín àgùntàn àti àgùntàn. 23 Èmi yóò yan olùṣọ́ àgùntàn kan fún wọn,+ Dáfídì ìránṣẹ́ mi,+ yóò sì máa bọ́ wọn. Òun fúnra rẹ̀ máa bọ́ wọn, ó sì máa di olùṣọ́ àgùntàn wọn.+ 24 Èmi Jèhófà yóò di Ọlọ́run wọn,+ Dáfídì ìránṣẹ́ mi yóò sì di ìjòyè láàárín wọn.+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.
25 “‘“Èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà,+ èmi yóò sì pa àwọn ẹranko ẹhànnà run ní ilẹ̀ náà,+ kí wọ́n lè máa gbé láìséwu nínú aginjù, kí wọ́n sì sùn nínú igbó.+ 26 Èmi yóò mú kí wọ́n di ìbùkún, màá mú kí ibi tó yí òkè mi ká náà di ìbùkún,+ màá sì mú kí òjò rọ̀ ní àkókò tó yẹ. Ìbùkún á rọ̀ bí òjò.+ 27 Àwọn igi oko yóò so èso, ilẹ̀ yóò mú èso jáde,+ wọn yóò sì máa gbé láìséwu lórí ilẹ̀ náà. Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà tí mo bá ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà wọn,+ tí mo sì gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó fi wọ́n ṣẹrú. 28 Àwọn orílẹ̀-èdè ò ní dọdẹ wọn mọ́, àwọn ẹran inú igbó ò ní pa wọ́n jẹ, ààbò yóò sì wà lórí wọn, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.+
29 “‘“Èmi yóò fún wọn ní oko tó lókìkí,* ìyàn ò ní pa wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ náà,+ àwọn orílẹ̀-èdè ò sì ní fi wọ́n ṣẹlẹ́yà mọ́.+ 30 ‘Wọn yóò wá mọ̀ pé èmi Jèhófà Ọlọ́run wọn wà pẹ̀lú wọn àti pé èèyàn mi ni wọ́n, ìyẹn ilé Ísírẹ́lì,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’
31 “‘Ní tiyín, ẹ̀yin àgùntàn mi,+ ẹ̀yin àgùntàn tí mò ń bójú tó, èèyàn lẹ jẹ́, èmi sì ni Ọlọ́run yín,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
35 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, yíjú rẹ sí agbègbè olókè Séírì,+ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí rẹ̀.+ 3 Sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò bá ọ jà, ìwọ agbègbè olókè Séírì, èmi yóò sì na ọwọ́ mi kí n lè fìyà jẹ ọ́, kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro.+ 4 Èmi yóò sọ àwọn ìlú rẹ di àwókù, wàá sì di ahoro;+ ìwọ yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà. 5 Torí pé ìwọ ò yéé kórìíra+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí o sì fà wọ́n lé idà lọ́wọ́ nígbà tí àjálù dé bá wọn, nígbà tí wọ́n jẹ ìyà ìkẹyìn.”’+
6 “‘Torí náà, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘èmi yóò mú kí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ rẹ sílẹ̀, ikú* yóò sì lépa rẹ.+ Nítorí pé o kórìíra ẹ̀jẹ̀, ikú yóò lépa rẹ.+ 7 Màá mú kí agbègbè olókè Séírì di ahoro,+ èmi yóò sì pa ẹnikẹ́ni tó bá ń kọjá lọ nínú rẹ̀ àti ẹnikẹ́ni tó bá ń pa dà bọ̀. 8 Èmi yóò fi òkú àwọn tí wọ́n pa kún àwọn òkè rẹ̀; àwọn tí wọ́n sì fi idà pa yóò ṣubú sórí àwọn òkè rẹ kéékèèké, sínú àwọn àfonífojì rẹ àti sínú gbogbo omi rẹ tó ń ṣàn. 9 Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé, wọn ò sì ní gbé inú àwọn ìlú rẹ;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
10 “Torí o sọ pé, ‘Orílẹ̀-èdè méjì yìí àti ilẹ̀ méjì yìí yóò di tèmi, méjèèjì á sì di ohun ìní wa,’+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ wà níbẹ̀, 11 ‘torí náà, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘bí o ṣe bínú sí wọn, tí o sì jowú wọn torí pé o kórìíra wọn ni èmi náà yóò ṣe sí ọ;+ màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ mí nígbà tí mo bá dá ọ lẹ́jọ́. 12 Ẹ ó wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò dáa tí ẹ sọ nípa àwọn òkè Ísírẹ́lì pé: “Wọ́n ti di ahoro, wọ́n sì ti fi wọ́n fún wa ká lè jẹ wọ́n run.”* 13 Ẹ fi ìgbéraga sọ̀rọ̀ sí mi, ẹ sì sọ̀rọ̀ sí mi gan-an.+ Gbogbo rẹ̀ ni mo gbọ́.’
14 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Inú gbogbo ayé yóò dùn nígbà tí mo bá sọ yín di ahoro. 15 Bí inú yín ṣe dùn nígbà tí ogún ilé Ísírẹ́lì di ahoro, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe sí yín.+ Ìwọ yóò di ahoro, ìwọ agbègbè olókè Séírì, àní gbogbo Édómù;+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”
36 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn òkè Ísírẹ́lì, kí o sì sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. 2 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ọ̀tá ti sọ̀rọ̀ sí yín pé, ‘Àháà! Kódà àwọn ibi gíga àtijọ́ ti di ohun ìní wa!’”’+
3 “Torí náà, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Torí pé wọ́n ti sọ yín di ahoro, wọ́n sì ti gbógun jà yín láti ibi gbogbo, kí ẹ lè di ohun ìní àwọn tó là á já* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ yín ṣáá, wọ́n sì ń bà yín lórúkọ jẹ́,+ 4 torí náà, ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké nìyí, fún àwọn ìṣàn omi àti àwọn àfonífojì, fún àwọn àwókù tó ti di ahoro+ àti fún àwọn ìlú tí wọ́n pa tì, tí àwọn tó là á já nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ti kó ní ẹrù, tí wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà;+ 5 ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn yìí ni pé: ‘Èmi yóò fi ìtara mi tó ń jó bí iná+ sọ̀rọ̀ sí àwọn tó là á já nínú àwọn orílẹ̀-èdè àti sí gbogbo Édómù, àwọn tí inú wọn dùn gan-an, tí wọ́n sì fi mí ṣẹlẹ́yà*+ nígbà tí wọ́n sọ ilẹ̀ mi di ohun ìní wọn, kí wọ́n lè gba àwọn ibi ìjẹko inú ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì kó ohun tó wà nínú rẹ̀.’”’+
6 “Torí náà, sọ tẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké, fún àwọn ìṣàn omi àti àwọn àfonífojì pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Wò ó! Èmi yóò fi ìtara àti ìbínú sọ̀rọ̀, torí àwọn orílẹ̀-èdè ti fi ọ́ ṣẹlẹ́yà.”’+
7 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Mo gbé ọwọ́ mi sókè láti búra pé ojú yóò ti àwọn orílẹ̀-èdè tó wà yí ká.+ 8 Àmọ́ ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ ó yọ ẹ̀ka, ẹ ó sì so èso fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì,+ torí wọn ò ní pẹ́ pa dà. 9 Torí mo wà pẹ̀lú yín, èmi yóò sì yíjú sí yín. Wọ́n á fi yín dáko, wọ́n á sì fún irúgbìn sínú yín. 10 Màá mú kí àwọn èèyàn rẹ pọ̀ sí i, gbogbo ilé Ísírẹ́lì, gbogbo rẹ̀ pátá, wọ́n á máa gbé inú àwọn ìlú náà,+ wọ́n á sì tún àwọn àwókù náà kọ́.+ 11 Àní màá sọ àwọn èèyàn rẹ àti ẹran ọ̀sìn rẹ di púpọ̀;+ wọ́n á bí sí i, wọ́n á sì pọ̀ sí i. Èmi yóò mú kí wọ́n máa gbé inú rẹ bíi ti tẹ́lẹ̀,+ èmi yóò sì mú kí nǹkan dáa fún yín ju ti tẹ́lẹ̀ lọ;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+ 12 Èmi yóò mú kí àwọn èèyàn mi, àní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, rìn lórí yín, wọ́n á sì sọ yín di ohun ìní.+ Ẹ ó di ogún wọn, ẹ ò sì tún ní sọ wọ́n di ẹni tí kò lọ́mọ mọ́.’”+
13 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí wọ́n ń sọ fún yín pé, “Ilẹ̀ tó ń jẹ àwọn èèyàn run tó sì ń mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣòfò ọmọ ni ìwọ jẹ́,”’ 14 ‘torí náà, o ò ní jẹ àwọn èèyàn run mọ́, o ò sì ní sọ àwọn èèyàn rẹ di ẹni tí kò lọ́mọ mọ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 15 ‘Mi ò ní mú kí àwọn orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀ èébú sí ọ mọ́, mi ò ní mú kí àwọn èèyàn kẹ́gàn rẹ mọ́,+ o ò sì ní mú àwọn èèyàn rẹ kọsẹ̀ mọ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
16 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 17 “Ọmọ èèyàn, nígbà tí ilé Ísírẹ́lì ń gbé lórí ilẹ̀ wọn, wọ́n fi ìwà àti ìṣe wọn sọ ọ́ di aláìmọ́.+ Lójú mi, ìwà wọn dà bí ìdọ̀tí tó ń jáde lára obìnrin tó ń ṣe nǹkan oṣù.+ 18 Torí náà, mo bínú sí wọn gan-an torí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sórí ilẹ̀ náà+ àti torí pé wọ́n fi òrìṣà ẹ̀gbin* wọn sọ ilẹ̀ náà di aláìmọ́.+ 19 Mo wá tú wọn ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, mo sì fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀.+ Mo fi ìwà àti ìṣe wọn dá wọn lẹ́jọ́. 20 Àmọ́ nígbà tí wọ́n wá sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yẹn, àwọn èèyàn kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ mi+ bí wọ́n ṣe ń sọ nípa wọn pé, ‘Àwọn èèyàn Jèhófà nìyí, àmọ́ wọ́n fi ilẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀.’ 21 Torí náà, màá káàánú orúkọ mímọ́ mi tí ilé Ísírẹ́lì kó ẹ̀gàn bá láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ.”+
22 “Torí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ilé Ísírẹ́lì, kì í ṣe torí yín ni mo ṣe gbé ìgbésẹ̀, àmọ́ torí orúkọ mímọ́ mi ni, èyí tí ẹ kó ẹ̀gàn bá láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ lọ.”’+ 23 ‘Ó dájú pé màá sọ orúkọ ńlá mi di mímọ́,+ èyí tí wọ́n kó ẹ̀gàn bá láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí ẹ kẹ́gàn rẹ̀ láàárín wọn; àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘nígbà tí mo bá fi hàn lójú wọn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín yín. 24 Èmi yóò kó yín látinú àwọn orílẹ̀-èdè, màá pa dà kó yín jọ láti gbogbo ilẹ̀, màá sì mú yín wá sórí ilẹ̀ yín.+ 25 Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára, ẹ ó sì mọ́;+ màá wẹ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìdọ̀tí yín+ àti gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin yín.+ 26 Èmi yóò fún yín ní ọkàn tuntun,+ màá sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín.+ Màá mú ọkàn òkúta+ kúrò lára yín, màá sì fún yín ní ọkàn ẹran.* 27 Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, màá sì mú kí ẹ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà mi.+ Ẹ ó máa tẹ̀ lé ìdájọ́ mi, ẹ ó sì máa pa wọ́n mọ́. 28 Ẹ ó wá máa gbé ní ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín, ẹ ó di èèyàn mi, màá sì di Ọlọ́run yín.’+
29 “‘Èmi yóò gbà yín kúrò nínú gbogbo ìdọ̀tí yín, màá fún yín ní ọkà, èmi yóò sì mú kó pọ̀ gidigidi, mi ò sì ní jẹ́ kí ìyàn mú ní ilẹ̀ yín.+ 30 Èmi yóò mú kí èso igi àti irè oko pọ̀ jaburata, kí ojú má bàa tì yín mọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè torí ìyàn.+ 31 Ẹ ó wá rántí àwọn ìwà búburú yín àti àwọn ohun tí kò dáa tí ẹ ṣe, ẹ ó sì kórìíra ara yín torí pé ẹ jẹ̀bi àti torí ìwà ìríra yín.+ 32 Àmọ́ mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé: Kì í ṣe torí yín ni mo fi ń ṣe èyí,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Àmọ́, kí ojú tì yín, ilé Ísírẹ́lì, kí ẹ sì tẹ́ torí ìwà yín.’
33 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ní ọjọ́ tí mo bá wẹ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀bi yín, èmi yóò mú kí wọ́n máa gbé inú àwọn ìlú náà,+ màá sì mú kí wọ́n tún àwọn àwókù kọ́.+ 34 Wọ́n á dáko sí ilẹ̀ tó ti di ahoro tí gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ ń wò. 35 Àwọn èèyàn á sì sọ pé: “Ilẹ̀ tó ti di ahoro náà ti dà bí ọgbà Édẹ́nì,+ àwọn ìlú tó ti di àwókù, tó ti di ahoro, tí wọ́n sì ya lulẹ̀ ti wá ní odi, wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀.”+ 36 Àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́ kù ní àyíká yín yóò wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti kọ́ ohun tó ya lulẹ̀, mo sì ti gbin ohun tó ti di ahoro. Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀, mo sì ti ṣe é.’+
37 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Màá tún jẹ́ kí ilé Ísírẹ́lì sọ pé kí n ṣe nǹkan yìí fún wọn: Èmi yóò mú kí àwọn èèyàn wọn pọ̀ sí i bí agbo ẹran. 38 Bí agbo àwọn ẹni mímọ́, bí agbo Jerúsálẹ́mù* nígbà àjọ̀dún rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìlú tó ti di àwókù yóò kún fún agbo àwọn èèyàn;+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”
37 Ọwọ́ Jèhófà wà lára mi, Jèhófà sì fi ẹ̀mí rẹ̀ gbé mi lọ sí àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀,+ egungun sì kún ibẹ̀. 2 Ó mú mi yí ibẹ̀ ká, mo sì rí i pé egungun pọ̀ gan-an ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, wọ́n sì gbẹ gidigidi.+ 3 Ó bi mí pé: “Ọmọ èèyàn, ǹjẹ́ àwọn egungun yìí tún lè ní ìyè?” Mo fèsì pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ ni ẹni tó mọ̀.”+ 4 Ó wá sọ fún mi pé: “Sọ tẹ́lẹ̀ sórí àwọn egungun yìí, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà:
5 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn egungun yìí ni pé: “Èmi yóò mú kí èémí wọnú yín, ẹ ó sì di alààyè.+ 6 Màá fi iṣan sára yín, màá sì mú kí ẹ ní ẹran lára. Màá fi awọ bò yín, màá fi èémí sínú yín, ẹ ó sì di alààyè; ẹ ó wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”
7 Torí náà, mo sọ tẹ́lẹ̀ bó ṣe pa á láṣẹ fún mi. Gbàrà tí mo sọ tẹ́lẹ̀, ariwo kan dún, ó dún bí ìgbà tí nǹkan ń rọ́ gììrì, àwọn egungun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í tò pọ̀, egungun so mọ́ egungun. 8 Mo wá rí i tí iṣan àti ẹran bò wọ́n, awọ sì bò wọ́n. Àmọ́ kò tíì sí èémí kankan nínú wọn.
9 Ó wá sọ fún mi pé: “Sọ tẹ́lẹ̀ nípa afẹ́fẹ́. Sọ tẹ́lẹ̀, ọmọ èèyàn, kí o sì sọ fún afẹ́fẹ́ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ìwọ afẹ́fẹ́,* fẹ́ wá láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, kí o sì fẹ́ lu àwọn èèyàn yìí tí wọ́n pa, kí wọ́n lè di alààyè.”’”
10 Torí náà, mo sọ tẹ́lẹ̀ bó ṣe pa á láṣẹ fún mi, èémí* sì wọnú wọn, wọ́n wá di alààyè, wọ́n sì dìde dúró,+ ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an ni wọ́n.
11 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, gbogbo ilé Ísírẹ́lì ni àwọn egungun yìí.+ Wọ́n ń sọ pé, ‘Egungun wa ti gbẹ, a ò sì ní ìrètí mọ́.+ Wọ́n ti pa wá run pátápátá.’ 12 Torí náà, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ̀yin èèyàn mi, èmi yóò ṣí àwọn sàréè yín,+ màá sì jí yín dìde látinú àwọn sàréè yín, èmi yóò sì mú yín wá sórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì.+ 13 Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, ẹ̀yin èèyàn mi, nígbà tí mo bá ṣí àwọn sàréè yín, tí mo sì jí yín dìde látinú àwọn sàréè yín.”’+ 14 ‘Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, ẹ ó sì di alààyè,+ èmi yóò mú kí ẹ máa gbé lórí ilẹ̀ yín; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀, mo sì ti ṣe é,’ ni Jèhófà wí.”
15 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 16 “Ìwọ ọmọ èèyàn, mú igi kan, kí o sì kọ ọ̀rọ̀ sára rẹ̀ pé, ‘Ti Júdà àti ti àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀.’*+ Kí o wá mú igi míì, kí o sì kọ ọ̀rọ̀ sára rẹ̀ pé, ‘Ti Jósẹ́fù, igi Éfúrémù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀.’*+ 17 Kí o wá mú méjèèjì sún mọ́ra kí wọ́n lè di igi kan ṣoṣo ní ọwọ́ rẹ.+ 18 Tí àwọn èèyàn rẹ* bá sọ fún ọ pé, ‘Ṣé o ò ní sọ ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí fún wa ni?’ 19 sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú igi Jósẹ́fù, tó wà lọ́wọ́ Éfúrémù àti àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, èmi yóò sì fi wọ́n mọ́ igi Júdà; èmi yóò sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo,+ wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.”’ 20 Kí o di àwọn igi tí o kọ nǹkan sí lára mú kí wọ́n lè rí i.
21 “Kí o wá sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ, èmi yóò kó wọn jọ láti ibi gbogbo, èmi yóò sì mú wọn wá sórí ilẹ̀ wọn.+ 22 Èmi yóò sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ náà,+ lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì, ọba kan ni yóò máa ṣàkóso gbogbo wọn,+ wọn ò sì ní jẹ́ orílẹ̀-èdè méjì mọ́; bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní pín sí ìjọba méjì mọ́.+ 23 Wọn ò ní fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* wọn àti àwọn ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe àti gbogbo ìṣìnà wọn sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin mọ́.+ Èmi yóò gbà wọ́n nínú gbogbo ìwà àìṣòótọ́ wọn tó mú wọn dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì wẹ̀ wọ́n mọ́. Wọ́n á di èèyàn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn.+
24 “‘“Dáfídì ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ́ ọba wọn,+ gbogbo wọn á sì ní olùṣọ́ àgùntàn kan.+ Wọ́n á máa tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi, wọ́n á sì máa rí i pé àwọn ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.+ 25 Wọn yóò máa gbé lórí ilẹ̀ tí mo fún Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, ibi tí àwọn baba ńlá yín gbé,+ wọn yóò sì máa gbé lórí rẹ̀ títí láé,+ àwọn àti àwọn ọmọ* wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn;+ Dáfídì ìránṣẹ́ mi ni yóò sì jẹ́ ìjòyè* wọn títí láé.+
26 “‘“Èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà;+ májẹ̀mú ayérayé ni màá bá wọn dá. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, màá sọ wọ́n di púpọ̀,+ màá sì fi ibi mímọ́ mi sí àárín wọn títí láé. 27 Àgọ́* mi yóò wà pẹ̀lú* wọn, èmi yóò di Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì di èèyàn mi.+ 28 Àwọn orílẹ̀-èdè á sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà, ni mò ń sọ Ísírẹ́lì di mímọ́ nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà ní àárín wọn títí láé.”’”+
38 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, dojú kọ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù,+ olórí ìjòyè* Méṣékì àti Túbálì,+ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i.+ 3 Sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò bá ọ jà, ìwọ Gọ́ọ̀gù, olórí ìjòyè* Méṣékì àti Túbálì. 4 Èmi yóò yí ojú rẹ pa dà, màá fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu,+ èmi yóò sì mú ìwọ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ jáde,+ àwọn ẹṣin àti àwọn tó ń gẹṣin tí gbogbo wọn wọṣọ iyì, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn pẹ̀lú àwọn apata ńlá àti asà,* gbogbo wọn ní idà; 5 Páṣíà, Etiópíà àti Pútì+ wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn ní asà* àti akoto;* 6 Gómérì àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀, ilé Tógámà+ láti ibi tó jìnnà jù ní àríwá, pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀; ọ̀pọ̀ èèyàn wà pẹ̀lú rẹ.+
7 “‘“Ẹ dira ogun, kí ẹ múra sílẹ̀, ìwọ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ tí wọ́n kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ, ìwọ lo sì máa ṣe ọ̀gágun* wọn.
8 “‘“Wàá gbàfiyèsí* lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́. Ní àwọn ọdún tó kẹ́yìn, ìwọ yóò gbógun ja àwọn èèyàn tó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, àwọn tó kóra jọ láti inú ọ̀pọ̀ èèyàn sórí àwọn òkè Ísírẹ́lì, tó ti di ahoro tipẹ́. Àárín àwọn èèyàn ni àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí ti jáde, ààbò sì wà lórí gbogbo wọn.+ 9 Ìwọ yóò ya bò wọ́n bí ìjì, wàá sì bo ilẹ̀ náà bí ìkùukùu,* ìwọ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ.”’
10 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ní ọjọ́ yẹn, wàá gbèrò àwọn nǹkan lọ́kàn rẹ, wàá sì gbìmọ̀ ibi. 11 O máa sọ pé: “Èmi yóò gbógun ja ilẹ̀ tí àwọn agbègbè rẹ̀ ṣí sílẹ̀.*+ Èmi yóò wá bá àwọn tó ń gbé láìséwu jà, àwọn tí kò sẹ́nì kankan tó ń yọ wọ́n lẹ́nu, gbogbo wọn ń gbé agbègbè tí kò ní ògiri, ọ̀pá ìdábùú tàbí àwọn ẹnubodè.” 12 Ó máa jẹ́ torí kó lè rí ẹrù tó pọ̀, kó sì kó o, láti gbógun ti àwọn ibi tó ti di ahoro àmọ́ tí wọ́n ti wá ń gbé ibẹ̀+ àti láti gbógun ti àwọn èèyàn tí wọ́n tún kó jọ láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ tí wọ́n ń kó ọrọ̀ àti dúkìá jọ,+ àwọn tó ń gbé ní àárín ayé.
13 “‘Ṣébà+ àti Dédánì,+ àwọn oníṣòwò Táṣíṣì + àti gbogbo ọmọ ogun* rẹ̀ yóò sọ fún ọ pé: “Ṣé kí o lè rí ẹrù tó pọ̀ kí o sì kó o lo ṣe fẹ́ gbógun jà wọ́n? Ṣé kí o lè kó fàdákà àti wúrà lo ṣe kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ, kí o lè kó ọrọ̀ àti dúkìá, kí o sì rí ẹrù rẹpẹtẹ kó?”’
14 “Torí náà, ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún Gọ́ọ̀gù pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ní ọjọ́ yẹn, tí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bá ń gbé láìséwu, ṣé o ò ní mọ̀?+ 15 O máa wá láti àyè rẹ, láti ibi tó jìnnà jù ní àríwá,+ ìwọ àti ọ̀pọ̀ èèyàn pẹ̀lú rẹ, tí gbogbo wọn gun ẹṣin, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn, àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an.+ 16 Ìwọ yóò wá gbéjà ko àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí ìgbà tí ìkùukùu* bo ilẹ̀. Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, èmi yóò mú kí o wá gbéjà ko ilẹ̀ mi,+ kí àwọn orílẹ̀-èdè lè mọ̀ mí, kí wọ́n sì mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí mo ṣe sí ọ, ìwọ Gọ́ọ̀gù.”’+
17 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ṣebí ìwọ náà ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà àtijọ́ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì Ísírẹ́lì tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún pé wọ́n á mú ọ wá láti bá wọn jà?’
18 “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ pé, ‘Ní ọjọ́ yẹn, ní ọjọ́ tí Gọ́ọ̀gù bá wá gbógun ja ilẹ̀ Ísírẹ́lì, inú á bí mi gidigidi.+ 19 Ìtara àti ìbínú mi tó ń jó bí iná ni màá fi sọ̀rọ̀. Ní ọjọ́ yẹn, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára gan-an yóò ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. 20 Àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹran inú igbó, gbogbo ẹran tó ń fàyà fà àti gbogbo èèyàn tó wà láyé yóò gbọ̀n rìrì nítorí mi, àwọn òkè yóò wó lulẹ̀,+ àwọn òkè tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ yóò ṣubú lulẹ̀, gbogbo ògiri yóò sì wó lulẹ̀.’
21 “‘Èmi yóò mú kí idà kan dojú kọ ọ́ lórí gbogbo òkè mi,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Kálukú yóò fi idà rẹ̀ bá arákùnrin rẹ̀ jà.+ 22 Èmi yóò fi àjàkálẹ̀ àrùn+ àti ikú dá a lẹ́jọ́; èmi yóò mú kí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá, òkúta yìnyín,+ iná+ àti imí ọjọ́+ rọ̀ lé òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lórí àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 23 Ó dájú pé màá gbé ara mi ga, màá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí, màá sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ irú ẹni tí mo jẹ́; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
39 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Gọ́ọ̀gù,+ kí o sì sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò bá ọ jà, Gọ́ọ̀gù, ìwọ olórí ìjòyè* Méṣékì àti Túbálì.+ 2 Èmi yóò mú kí o yíjú pa dà, màá darí rẹ, màá sì mú kí o wá láti ibi tó jìnnà jù ní àríwá,+ èmi yóò sì mú ọ wá sórí àwọn òkè Ísírẹ́lì. 3 Èmi yóò gbá ọrun rẹ dà nù ní ọwọ́ òsì rẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn ọfà rẹ já bọ́ kúrò ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ. 4 Ìwọ yóò ṣubú sí orí àwọn òkè Ísírẹ́lì,+ ìwọ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ àti àwọn èèyàn tí yóò wà pẹ̀lú rẹ. Màá mú kí onírúurú ẹyẹ aṣọdẹ àti ẹran inú igbó fi ọ́ ṣe oúnjẹ.”’+
5 “‘Wàá ṣubú sórí pápá gbalasa,+ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
6 “‘Màá mú kí iná jó Mágọ́gù àti àwọn tó ń gbé àwọn erékùṣù láìséwu,+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà. 7 Màá mú kí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì mọ orúkọ mímọ́ mi, mi ò sì tún ní jẹ́ kí wọ́n kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ mi mọ́; àwọn orílẹ̀-èdè á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ Ẹni Mímọ́ ní Ísírẹ́lì.’+
8 “‘Àní, ó ń bọ̀, yóò sì ṣẹlẹ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Ọjọ́ tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nìyí. 9 Àwọn tó ń gbé ní àwọn ìlú Ísírẹ́lì yóò jáde lọ, wọ́n á sì fi àwọn ohun ìjà dáná, àwọn asà* àti àwọn apata, àwọn ọrun àti àwọn ọfà, àwọn kóńdó* àti àwọn aṣóró. Wọn yóò sì fi wọ́n dáná+ fún ọdún méje. 10 Wọn kò ní máa lọ ṣa igi lóko tàbí kí wọ́n ṣẹ́gi ìdáná nínú igbó torí àwọn ohun ìjà náà ni wọ́n á fi dáná.’
“‘Wọn yóò kó ẹrù àwọn tó ti kó wọn lẹ́rù rí, wọn yóò sì kó ohun ìní àwọn tó máa ń kó ohun ìní wọn,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
11 “‘Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò yan ibì kan níbẹ̀ ní Ísírẹ́lì tí wọn yóò sin Gọ́ọ̀gù+ sí, ní àfonífojì tí àwọn tó ń rìnrìn àjò ní ìlà oòrùn òkun ń gbà kọjá, yóò sì dí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọjá. Ibẹ̀ ni wọn yóò sin Gọ́ọ̀gù àti gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ sí, wọ́n á sì máa pe ibẹ̀ ní Àfonífojì Hamoni-Gọ́ọ̀gù.*+ 12 Oṣù méje ni ilé Ísírẹ́lì máa fi sin wọ́n kí wọ́n lè fọ ilẹ̀ náà mọ́.+ 13 Gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà ni yóò sin wọ́n, èyí sì máa mú kí wọ́n lókìkí ní ọjọ́ tí mo bá ṣe ara mi lógo,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
14 “‘Wọ́n á yan àwọn èèyàn tí yóò máa lọ káàkiri ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè sin àwọn òkú tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀, láti fọ ilẹ̀ náà mọ́. Oṣù méje ni wọ́n á fi máa lọ káàkiri. 15 Tí àwọn tó ń lọ káàkiri ilẹ̀ náà bá rí egungun èèyàn, wọ́n á fi àmì kan sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àwọn tí wọ́n yàn láti sin òkú yóò wá lọ sin ín sí Àfonífojì Hamoni-Gọ́ọ̀gù.+ 16 Ìlú kan tún máa wà níbẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́ Hámónà.* Wọ́n á sì fọ ilẹ̀ náà mọ́.’+
17 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Sọ fún onírúurú ẹyẹ àti gbogbo ẹran inú igbó pé, “Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ sì wá. Ẹ kóra jọ yí ká ẹbọ mi tí mò ń pèsè fún yín, ẹbọ tó pọ̀ gan-an lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì.+ Ẹ ó jẹ ẹran, ẹ ó sì mu ẹ̀jẹ̀.+ 18 Ẹ ó jẹ ẹran àwọn alágbára, ẹ ó sì mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ìjòyè ayé, àwọn àgbò, àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn, àwọn òbúkọ àti àwọn akọ màlúù, gbogbo ẹran Báṣánì tí wọ́n bọ́ sanra. 19 Ẹ ó jẹ ọ̀rá ní àjẹyó, ẹ ó sì mu ẹ̀jẹ̀ yó nínú ẹbọ tí mo pèsè fún yín.”’
20 “‘Ẹ ó jẹ ẹṣin àti àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin, àwọn alágbára àti onírúurú jagunjagun lórí tábìlì mi, ẹ ó sì yó,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
21 “‘Èmi yóò fi ògo mi hàn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì rí ìdájọ́ tí mo ṣe àti bí mo ṣe fi agbára* hàn láàárín wọn.+ 22 Láti ọjọ́ yẹn lọ, ilé Ísírẹ́lì á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn. 23 Àwọn orílẹ̀-èdè á sì wá mọ̀ pé torí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì, torí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí mi ni wọ́n fi lọ sí ìgbèkùn.+ Torí náà, mo fi ojú mi pa mọ́ fún wọn,+ mo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́,+ idà sì pa gbogbo wọn. 24 Mo fìyà jẹ wọ́n nítorí ìwà àìmọ́ wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, mo sì fi ojú mi pa mọ́ fún wọn.’
25 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò dá àwọn èèyàn Jékọ́bù tí wọ́n kó lẹ́rú pa dà,+ màá sì ṣàánú gbogbo ilé Ísírẹ́lì;+ èmi yóò fi ìtara gbèjà orúkọ mímọ́ mi.*+ 26 Lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti dójú tì wọ́n torí gbogbo ìwà àìṣòótọ́ tí wọ́n hù sí mi,+ wọn yóò máa gbé lórí ilẹ̀ wọn láìséwu, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.+ 27 Nígbà tí mo bá mú wọn pa dà láti ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn, tí mo sì kó wọn jọ láti ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn,+ èmi yóò tún mú kí wọ́n mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí lójú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.’+
28 “‘Wọ́n á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn nígbà tí mo bá mú kí wọ́n lọ sí ìgbèkùn ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì kó wọn jọ pa dà sórí ilẹ̀ wọn, láìfi ìkankan nínú wọn sílẹ̀.+ 29 Mi ò ní fi ojú mi pa mọ́ fún wọn mọ́,+ torí màá tú ẹ̀mí mi sórí ilé Ísírẹ́lì,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
40 Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí a ti wà nígbèkùn,+ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún náà, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù, ní ọdún kẹrìnlá lẹ́yìn tí ìlú náà ti pa run,+ ọjọ́ yẹn gan-an ni ọwọ́ Jèhófà wà lára mi, ó sì mú mi lọ sí ìlú náà.+ 2 Nínú àwọn ìran tí Ọlọ́run fi hàn mí, ó mú mi wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ó sì gbé mi sórí òkè kan tó ga fíofío.+ Ohun kan wà lórí òkè náà tó dà bí ìlú kan ní apá gúúsù.
3 Nígbà tó mú mi dé ibẹ̀, mo rí ọkùnrin kan tí ìrísí rẹ̀ dà bíi bàbà.+ Ó mú okùn ọ̀gbọ̀ àti ọ̀pá esùsú* tí wọ́n fi ń wọn nǹkan dání,+ ó sì dúró ní ẹnubodè. 4 Ọkùnrin náà sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, la ojú rẹ sílẹ̀ dáadáa, tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́, kí o sì fiyè sí* gbogbo ohun tí mo bá fi hàn ọ́, torí ìdí tí mo ṣe mú ọ wá síbí nìyẹn. Gbogbo ohun tí o bá rí ni kí o sọ fún ilé Ísírẹ́lì.”+
5 Mo rí ògiri kan tó yí ìta tẹ́ńpìlì* náà ká. Ọkùnrin náà mú ọ̀pá esùsú tí wọ́n fi ń wọn nǹkan dání, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà (wọ́n fi ìbú ọwọ́ kan kún ìgbọ̀nwọ́ kọ̀ọ̀kan).* Ó bẹ̀rẹ̀ sí í wọn ògiri náà, nínípọn rẹ̀ jẹ́ ọ̀pá esùsú kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀pá esùsú kan.
6 Ó wá sí ẹnubodè tó kọjú sí ìlà oòrùn,+ ó sì gun àtẹ̀gùn tó wà níbẹ̀. Nígbà tó wọn ẹnubodè náà, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọ̀pá esùsú kan, fífẹ̀ ẹnu ọ̀nà kejì náà sì jẹ́ ọ̀pá esùsú kan. 7 Gígùn yàrá ẹ̀ṣọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọ̀pá esùsú kan, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọ̀pá esùsú kan. Àlàfo tó wà láàárín àwọn yàrá náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.+ Ẹnubodè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi àbáwọlé* ẹnu ọ̀nà tó kọjú sínú jẹ́ ọ̀pá esùsú kan.
8 Ó wọn ibi àbáwọlé* ní ẹnu ọ̀nà tó wà nínú, ó jẹ́ ọ̀pá esùsú kan. 9 Ó wá wọn ibi àbáwọlé* ẹnubodè náà, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ; ó sì wọn àwọn òpó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì; ibi àbáwọlé* ẹnubodè náà sì wà ní ẹ̀gbẹ́ tó kọjú sínú.
10 Yàrá ẹ̀ṣọ́ mẹ́ta ló wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ẹnubodè tó wà ní ìlà oòrùn. Ìwọ̀n mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dọ́gba, ìwọ̀n àwọn òpó tó wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì sì dọ́gba.
11 Ó wá wọn fífẹ̀ ibi ẹnubodè náà, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá; gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́tàlá (13).
12 Àyè tó wà níwájú àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ náà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ tó wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà.
13 Ó wá wọn ibi ẹnubodè náà láti òrùlé yàrá ẹ̀ṣọ́ kan* dé òrùlé ti èkejì, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25); ẹnu ọ̀nà méjì kọjú síra.+ 14 Lẹ́yìn náà, ó wọn àwọn òpó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì, gíga wọn jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́. Ó tún wọn àwọn òpó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè tó yí àgbàlá náà ká. 15 Láti iwájú ibi ẹnubodè náà dé iwájú ibi àbáwọlé* ẹnubodè tó wà nínú jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́.
16 Fèrèsé* tí férémù wọn fẹ̀ lápá kan tó sì kéré lódìkejì*+ wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ àti àwọn òpó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn nínú ẹnubodè náà. Fèrèsé tún wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ní inú ibi àbáwọlé ẹnu ọ̀nà náà, àwọn òpó tó sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ní àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ lára.+
17 Ó wá mú mi wá sí àgbàlá ìta, mo sì rí àwọn yàrá ìjẹun*+ àti pèpéle tó yí àgbàlá náà ká. Ọgbọ̀n (30) yàrá ìjẹun ló wà lórí pèpéle náà. 18 Ìwọ̀n pèpéle tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè náà dọ́gba pẹ̀lú gígùn àwọn ẹnubodè náà, pèpéle yìí ló wà nísàlẹ̀.
19 Ó wá wọn* iwájú ẹnubodè ìsàlẹ̀ dé iwájú àgbàlá inú, ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ ní ìlà oòrùn àti ní àríwá.
20 Àgbàlá ìta ní ẹnubodè tó dojú kọ àríwá, ó sì wọn gígùn rẹ̀ àti fífẹ̀ rẹ̀. 21 Yàrá ẹ̀ṣọ́ mẹ́ta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. Ìwọ̀n àwọn òpó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan àti ibi àbáwọlé* rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú ìwọ̀n ẹnubodè àkọ́kọ́. Gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25). 22 Àwọn fèrèsé rẹ̀, ibi àbáwọlé* rẹ̀ àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ+ tó wà lára rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú àwọn ti ẹnubodè ìlà oòrùn. Àtẹ̀gùn méje ni èèyàn máa gùn kó tó débẹ̀, ibi àbáwọlé* rẹ̀ sì wà níwájú wọn.
23 Ẹnubodè kan wà ní àgbàlá inú tó dojú kọ ẹnubodè àríwá, òmíràn sì dojú kọ ẹnubodè ìlà oòrùn. Ó wá wọn àyè tó wà láàárín ẹnubodè kan sí ìkejì, ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́.
24 Lẹ́yìn ìyẹn, ó mú mi wá sí apá gúúsù,+ mo sì rí ẹnubodè kan níbẹ̀. Ó wọn àwọn òpó ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti ibi àbáwọlé* rẹ̀, wọ́n sì dọ́gba pẹ̀lú àwọn yòókù. 25 Fèrèsé wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti ibi àbáwọlé* rẹ̀, bí àwọn fèrèsé yòókù. Gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25). 26 Àtẹ̀gùn méje ló dé ibẹ̀,+ ibi àbáwọlé* rẹ̀ sì wà níwájú wọn. Àwọn òpó tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjèèjì ní àwòrán igi ọ̀pẹ kọ̀ọ̀kan lára.
27 Àgbàlá inú ní ẹnubodè kan tó dojú kọ gúúsù; ó wọn ẹnubodè kan sí ìkejì sí apá gúúsù, ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́. 28 Lẹ́yìn ìyẹn, ó mú mi gba ẹnubodè gúúsù wá sí àgbàlá inú; nígbà tó wọn ẹnubodè gúúsù, ó dọ́gba pẹ̀lú àwọn yòókù. 29 Àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ rẹ̀, àwọn òpó ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti ibi àbáwọlé* ẹnu ọ̀nà rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú àwọn yòókù. Fèrèsé wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àti ibi àbáwọlé* rẹ̀. Gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25).+ 30 Ibi àbáwọlé* wà yí ká; gígùn wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), fífẹ̀ wọn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. 31 Ibi àbáwọlé* rẹ̀ dojú kọ àgbàlá ìta, àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ wà lára àwọn òpó ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,+ àtẹ̀gùn mẹ́jọ ló sì dé ibẹ̀.+
32 Nígbà tó mú mi wá sí àgbàlá inú láti ìlà oòrùn, ó wọn ẹnubodè náà, ó sì dọ́gba pẹ̀lú àwọn yòókù. 33 Àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ rẹ̀, àwọn òpó ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti ibi àbáwọlé* rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú àwọn yòókù, fèrèsé sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àti ibi àbáwọlé* rẹ̀. Gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25). 34 Ibi àbáwọlé* rẹ̀ dojú kọ àgbàlá ìta, àwòrán igi ọ̀pẹ sì wà lára àwọn òpó ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ló sì dé ibẹ̀.
35 Ó wá mú mi wá sínú ẹnubodè àríwá,+ ó sì wọ̀n ọ́n; ó dọ́gba pẹ̀lú àwọn yòókù. 36 Àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ rẹ̀, àwọn òpó ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti ibi àbáwọlé* rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú àwọn yòókù. Ó ní fèrèsé ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. Gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25). 37 Àwọn òpó ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kọjú sí àgbàlá ìta, àwòrán igi ọ̀pẹ wà lára àwọn òpó ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ló sì dé ibẹ̀.
38 Yàrá ìjẹun kan àti ẹnu ọ̀nà rẹ̀ wà nítòsí àwọn òpó tó wà ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ẹnubodè náà, níbi tí wọ́n ti ń fọ odindi ẹbọ sísun.+
39 Tábìlì méjì wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ibi àbáwọlé* ẹnubodè náà. Orí wọn ni wọ́n ti máa ń pa ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rú odindi ẹbọ sísun,+ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti ẹbọ ẹ̀bi.+ 40 Ní ọ̀nà tó lọ sí ibi àbáwọlé ẹnubodè àríwá, tábìlì méjì wà níta. Tábìlì méjì tún wà ní òdìkejì ibi àbáwọlé* ẹnubodè náà. 41 Tábìlì mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan ẹnubodè náà, gbogbo rẹ̀ jẹ́ tábìlì mẹ́jọ, orí wọn sì ni wọ́n ti ń pa ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ. 42 Òkúta ni wọ́n fi gbẹ́ tábìlì mẹ́rin tí wọ́n ń lò fún odindi ẹbọ sísun. Gígùn wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀, fífẹ̀ wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀, gíga wọn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan. Àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń kó sórí wọn ni àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rú ẹbọ sísun àtàwọn ẹbọ míì. 43 Ibi tí wọ́n lè to nǹkan sí wà lára àwọn ògiri inú yí ká, wọ́n sì fẹ̀ tó ìbú ọwọ́ kan; wọ́n máa ń gbé ẹran ọrẹ ẹ̀bùn sí orí àwọn tábìlì náà.
44 Àwọn yàrá ìjẹun àwọn akọrin wà níta ẹnubodè tó wà nínú;+ wọ́n wà ní àgbàlá inú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè àríwá, wọ́n dojú kọ gúúsù. Yàrá ìjẹun míì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè ìlà oòrùn, ó dojú kọ àríwá.
45 Ó sọ fún mi pé: “Yàrá ìjẹun tó dojú kọ gúúsù yìí wà fún àwọn àlùfáà tó ń bójú tó iṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì.+ 46 Yàrá ìjẹun tó dojú kọ àríwá wà fún àwọn àlùfáà tó ń bójú tó iṣẹ́ pẹpẹ.+ Àwọn ni ọmọ Sádókù,+ àwọn ni àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n yàn láti máa wá síwájú Jèhófà kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ fún un.”+
47 Ó wá wọn àgbàlá inú. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́, ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba. Pẹpẹ náà wà ní iwájú tẹ́ńpìlì.
48 Ó wá mú mi wá sí ibi àbáwọlé* tẹ́ńpìlì,+ ó sì wọn òpó ẹ̀gbẹ́ ibi àbáwọlé* náà, ẹ̀gbẹ́ kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ẹ̀gbẹ́ kejì sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Fífẹ̀ ẹnubodè náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kan àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kejì.
49 Gígùn ibi àbáwọlé* náà jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mọ́kànlá (11).* Àtẹ̀gùn ni àwọn èèyàn máa ń gùn dé ibẹ̀. Òpó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjèèjì, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan.+
41 Ó wá mú mi wọ ibi mímọ́ ìta,* ó sì wọn àwọn òpó tó wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì; fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* mẹ́fà ní ẹ̀gbẹ́ kan, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ẹ̀gbẹ́ kejì. 2 Fífẹ̀ ẹnu ọ̀nà náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, ògiri tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ẹ̀gbẹ́ kan àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ẹ̀gbẹ́ kejì. Ó wọn gígùn rẹ̀, ó jẹ́ ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́.
3 Ó wá wọlé,* ó sì wọn òpó tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà, ìnípọn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, fífẹ̀ ẹnu ọ̀nà náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà. Àwọn ògiri tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà náà jẹ́* ìgbọ̀nwọ́ méje. 4 Lẹ́yìn ìyẹn, ó wọn yàrá tó kọjú sí ibi mímọ́ ìta, gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́.+ Ó sì sọ fún mi pé: “Ibi Mímọ́ Jù Lọ nìyí.”+
5 Ó wá wọn ògiri tẹ́ńpìlì náà, ìnípọn rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà. Fífẹ̀ àwọn yàrá tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tẹ́ńpìlì náà yí ká jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin.+ 6 Àwọn yàrá náà ní àjà mẹ́ta, ọ̀kan wà lórí èkejì, ọgbọ̀n (30) yàrá ló sì wà nínú àjà kọ̀ọ̀kan. Ògiri tẹ́ńpìlì náà ní igun yí ká, èyí tó gbé àwọn yàrá náà dúró tó fi jẹ́ pé ohun tó gbé àwọn yàrá náà dúró kò wọnú ògiri tẹ́ńpìlì.+ 7 Àtẹ̀gùn* kan wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì tẹ́ńpìlì náà tó ń fẹ̀ sí i láti ìsàlẹ̀ lọ sókè.+ Bí èèyàn bá ṣe ń gùn ún láti àjà kan sí òmíràn ló ń fẹ̀ sí i, ó ń fẹ̀ sí i láti àjà ìsàlẹ̀ dé àjà àárín lọ sí àjà òkè.
8 Mo rí pèpéle kan, tó yí tẹ́ńpìlì náà ká, ìpìlẹ̀ àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà sì jẹ́ ọ̀pá esùsú kan tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà dé igun. 9 Ògiri ìta àwọn yàrá tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fẹ̀ ní ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Àyè* kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ tó wà lára tẹ́ńpìlì náà.
10 Àyè kan wà láàárín tẹ́ńpìlì náà àti àwọn yàrá ìjẹun,*+ fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. 11 Ẹnu ọ̀nà kan wà láàárín àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ àti àyè tó wà ní apá àríwá, ẹnu ọ̀nà mìíràn sì wà ní apá gúúsù. Fífẹ̀ àyè náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún yí ká.
12 Ilé tó wà ní ìwọ̀ oòrùn tó dojú kọ àyè fífẹ̀ náà jẹ́ àádọ́rin (70) ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́rùn-ún (90) ìgbọ̀nwọ́; ìnípọn ògiri ilé náà yí ká jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.
13 Ó wọn tẹ́ńpìlì náà, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́. Àyè fífẹ̀ náà, ilé náà* àti ògiri rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. 14 Iwájú tẹ́ńpìlì náà tó dojú kọ ìlà oòrùn àti àyè fífẹ̀ náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀.
15 Ó wọn ilé tó kọjú sí ẹ̀yìn àyè fífẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́.
Ó tún wọn ibi mímọ́ ìta, ibi mímọ́ inú+ àti àwọn ibi àbáwọlé* ní àgbàlá náà, 16 pẹ̀lú àwọn ẹnu ọ̀nà, àwọn fèrèsé* tí férémù wọn fẹ̀ lápá kan tó sì kéré lódìkejì*+ àti àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ tó wà ní àwọn ibi mẹ́ta yẹn. Igi pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ+ ni wọ́n fi ṣe ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà náà láti ilẹ̀ dé ibi fèrèsé; wọ́n sì bo àwọn fèrèsé náà. 17 Ó wọn òkè ẹnu ọ̀nà náà, inú tẹ́ńpìlì, ìta àti gbogbo ògiri yí ká. 18 Wọ́n gbẹ́ àwòrán àwọn kérúbù+ àti igi ọ̀pẹ+ sára rẹ̀, àwòrán igi ọ̀pẹ kan wà láàárín kérúbù méjì, kérúbù kọ̀ọ̀kan sì ní ojú méjì. 19 Ojú èèyàn kọjú sí àwòrán igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kan, ojú kìnnìún* sì kọjú sí àwòrán igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kejì.+ Bí wọ́n ṣe gbẹ́ ẹ sí ara tẹ́ńpìlì náà yí ká nìyẹn. 20 Wọ́n gbẹ́ àwòrán àwọn kérúbù àti igi ọ̀pẹ sára ògiri ibi mímọ́ láti ilẹ̀ dé ibi òkè ẹnu ọ̀nà.
21 Igun mẹ́rin ni àwọn férémù* ibi mímọ́ náà ní.+ Ohun kan wà níwájú ibi mímọ́* náà tó dà bíi 22 pẹpẹ onígi+ tí gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta, tí gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì. Ó ní igun, igi ni wọ́n sì fi ṣe ìsàlẹ̀* rẹ̀ àti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ó wá sọ fún mi pé: “Tábìlì tó wà níwájú Jèhófà nìyí.”+
23 Ibi mímọ́ ìta àti ibi mímọ́ jù lọ ní ilẹ̀kùn méjì-méjì.+ 24 Ẹnu ọ̀nà náà ní ilẹ̀kùn méjì tó ṣeé ṣí síbí sọ́hùn-ún, ilẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan sì ní awẹ́ méjì. 25 Wọ́n gbẹ́ àwòrán àwọn kérúbù àti igi ọ̀pẹ sára àwọn ilẹ̀kùn ibi mímọ́, bíi ti èyí tó wà lára àwọn ògiri.+ Ìbòrí kan tí wọ́n fi pákó ṣe wà níwájú ibi àbáwọlé* níta. 26 Àwọn fèrèsé tí férémù wọn fẹ̀ lápá kan tó sì kéré lódìkejì*+ àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ tún wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ibi àbáwọlé* náà àti àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ inú tẹ́ńpìlì àti àwọn ìbòrí náà.
42 Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí àgbàlá ìta ní apá àríwá.+ Ó mú mi wá sí ilé tó ní àwọn yàrá ìjẹun tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àyè fífẹ̀ náà,+ ó wà ní àríwá ilé tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ 2 Gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́* láti ẹnu ọ̀nà àríwá, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́. 3 Ó wà láàárín àgbàlá inú tó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́+ àti pèpéle àgbàlá ìta. Àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ rẹ̀ dojú kọra, wọ́n sì ní àjà mẹ́ta. 4 Ọ̀nà kan gba iwájú àwọn yàrá ìjẹun* náà+ tí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá tí gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́,* ẹnu ọ̀nà àwọn yàrá náà sì dojú kọ àríwá. 5 Àwọn yàrá ìjẹun tó wà lókè pátápátá kéré sí àwọn èyí tó wà ní àjà àárín àti ti ìsàlẹ̀, torí pé ọ̀dẹ̀dẹ̀ wọn ti gbà lára àyè wọn. 6 Àjà mẹ́ta ló ní, àmọ́ wọn ò ní òpó bí àwọn òpó tó wà ní àgbàlá. Ìdí nìyẹn tí wọn kò fi ní àyè púpọ̀ bíi ti àjà ìsàlẹ̀ àti ti àárín.
7 Ògiri olókùúta tó wà níta lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn yàrá ìjẹun ní apá àgbàlá ìta tó dojú kọ àwọn yàrá ìjẹun yòókù jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. 8 Àwọn yàrá ìjẹun tó wà ní apá àgbàlá ìta jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, àmọ́ àwọn tó dojú kọ ibi mímọ́ jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. 9 Ọ̀nà kan wà ní ìlà oòrùn tí wọ́n lè gbà wọ àwọn yàrá ìjẹun náà láti àgbàlá ìta.
10 Àwọn yàrá ìjẹun tún wà lẹ́gbẹ̀ẹ́* ògiri olókùúta tó wà ní àgbàlá ní apá ìlà oòrùn, nítòsí àyè fífẹ̀ àti ilé náà.+ 11 Ọ̀nà kan gba iwájú wọn bíi ti àwọn yàrá ìjẹun tó wà ní àríwá.+ Wọ́n gùn bákan náà, wọ́n sì fẹ̀ bákan náà, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jáde níbẹ̀ àti bí wọ́n ṣe kọ́ ọ rí bákan náà. Ẹnu ọ̀nà wọn 12 dà bí ẹnu ọ̀nà àwọn yàrá ìjẹun tó wà ní apá gúúsù. Ẹnu ọ̀nà kan wà níbi tí ojú ọ̀nà náà ti bẹ̀rẹ̀ tí èèyàn lè gbà wọlé, níwájú ògiri olókùúta tó wà ní apá ìlà oòrùn.+
13 Ó wá sọ fún mi pé: “Yàrá ìjẹun mímọ́ ni àwọn yàrá ìjẹun tó wà ní àríwá àti àwọn èyí tó wà ní gúúsù tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àyè fífẹ̀ yẹn,+ ibẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí wọ́n ń wá síwájú Jèhófà ti máa ń jẹ àwọn ọrẹ mímọ́ jù lọ.+ Ibẹ̀ ni wọ́n ń gbé àwọn ọrẹ mímọ́ jù lọ sí àti ọrẹ ọkà, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi, torí pé ibi mímọ́ ni.+ 14 Tí àwọn àlùfáà bá wọlé, kí wọ́n má ṣe jáde kúrò ní ibi mímọ́ lọ sí àgbàlá ìta láìkọ́kọ́ bọ́ aṣọ tí wọ́n fi ṣiṣẹ́,+ torí aṣọ mímọ́ ni. Wọ́n á wọ aṣọ míì kí wọ́n tó sún mọ́ ibi tí àwọn èèyàn lè dé.”
15 Nígbà tó wọn àwọn ibi tó wà ní inú tẹ́ńpìlì* tán, ó mú mi jáde gba ẹnubodè tó dojú kọ ìlà oòrùn,+ ó sì wọn gbogbo ibẹ̀.
16 Ó fi ọ̀pá esùsú* náà wọn apá ìlà oòrùn. Nígbà tó fi ọ̀pá náà wọ̀n ọ́n, gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú láti ẹ̀gbẹ́ kan dé ìkejì.
17 Ó fi ọ̀pá esùsú náà wọn apá àríwá, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú.
18 Ó fi ọ̀pá esùsú náà wọn apá gúúsù, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú.
19 Ó lọ yí ká apá ìwọ̀ oòrùn. Ó fi ọ̀pá esùsú náà wọ̀n ọ́n, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú.
20 Ó wọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ó ní ògiri yí ká,+ ògiri náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú ní gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú.+ Wọ́n fi ògiri náà pààlà sáàárín ohun tó jẹ́ mímọ́ àti ohun tó jẹ́ ti gbogbo èèyàn.+
43 Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ẹnubodè tó dojú kọ ìlà oòrùn.+ 2 Mo rí ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì níbẹ̀ tó ń bọ̀ láti ìlà oòrùn,+ ohùn rẹ̀ sì dà bí ìró omi tó ń rọ́ jáde;+ ògo rẹ̀ sì tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé.+ 3 Ohun tí mo rí dà bí ìran tí mo rí nígbà tí mo* wá pa ìlú náà run, ó sì dà bí ohun tí mo rí lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Kébárì;+ mo sì dojú bolẹ̀.
4 Ògo Jèhófà wá gba ẹnubodè tó dojú kọ ìlà oòrùn wọnú tẹ́ńpìlì* náà.+ 5 Ẹ̀mí kan gbé mi sókè, ó mú mi wá sí àgbàlá inú, mo sì rí i pé ògo Jèhófà kún inú tẹ́ńpìlì náà.+ 6 Mo wá gbọ́ tí ẹnì kan ń bá mi sọ̀rọ̀ láti inú tẹ́ńpìlì náà, ọkùnrin náà sì wá dúró sí ẹ̀gbẹ́ mi.+ 7 Ó sọ fún mi pé:
“Ọmọ èèyàn, ibi ìtẹ́ mi+ àti ibi tí màá gbé ẹsẹ̀ mi sí nìyí,+ ibẹ̀ ni èmi yóò máa gbé títí láé láàárín àwọn èèyàn Ísírẹ́lì.+ Ilé Ísírẹ́lì àti àwọn ọba wọn kò ní fi àgbèrè ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe àti òkú àwọn ọba wọn nígbà tí wọ́n bá kú sọ orúkọ mímọ́ mi di ẹlẹ́gbin mọ́.+ 8 Wọ́n fi ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe sọ orúkọ mímọ́ mi di ẹlẹ́gbin bí wọ́n ṣe gbé ibi àbáwọlé wọn sí ẹ̀gbẹ́ ibi àbáwọlé mi, tí wọ́n sì gbé férémù ẹnu ọ̀nà wọn sí ẹ̀gbẹ́ férémù ẹnu ọ̀nà mi, ògiri nìkan ló sì wà láàárín èmi àti àwọn.+ Torí náà, inú bí mi, mo sì pa wọ́n run.+ 9 Kí wọ́n gbé àgbèrè ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe àti òkú àwọn ọba wọn jìnnà sí mi, èmi yóò sì máa gbé láàárín wọn títí láé.+
10 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, ṣàlàyé bí tẹ́ńpìlì náà ṣe rí fún ilé Ísírẹ́lì,+ kí ojú lè tì wọ́n torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,+ kí wọ́n sì ṣàyẹ̀wò àwòrán ìkọ́lé rẹ̀.* 11 Tí ojú bá tì wọ́n torí gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe, jẹ́ kí wọ́n mọ àwòrán ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì náà, fi bí wọ́n ṣe tò ó hàn wọ́n, kí o sì fi àwọn ẹnu ọ̀nà àbájáde àti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀ hàn wọ́n.+ Fi gbogbo àwòrán ìpìlẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ìlànà rẹ̀ hàn wọ́n, fi àwòrán ìpìlẹ̀ rẹ̀ àti àwọn òfin rẹ̀ hàn wọ́n, kí o sì kọ wọ́n sílẹ̀ níṣojú wọn, kí wọ́n lè máa fiyè sí gbogbo àwòrán ìpìlẹ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì máa pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́.+ 12 Òfin tẹ́ńpìlì náà nìyí. Gbogbo agbègbè tó yí orí òkè náà ká jẹ́ mímọ́ jù lọ.+ Wò ó! Òfin tẹ́ńpìlì náà nìyí.
13 “Ìwọ̀n pẹpẹ náà ní ìgbọ̀nwọ́ nìyí + (wọ́n fi ìbú ọwọ́ kan kún ìgbọ̀nwọ́ kan).* Ìgbọ̀nwọ́ kan ni ìsàlẹ̀ rẹ̀, ó sì fẹ̀ tó ìgbọ̀nwọ́ kan. Igun rẹ̀ ní etí yí ká, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.* Ìsàlẹ̀ pẹpẹ náà nìyí. 14 Láti ilẹ̀ dé etí ìgbásẹ̀ ìsàlẹ̀ tó yí i ká jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan. Láti ìgbásẹ̀ kékeré dé etí ìgbásẹ̀ ńlá jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan. 15 Ibi tí wọ́n ti ń dáná lórí pẹpẹ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga, ìwo mẹ́rin sì wà níbi ìdáná náà.+ 16 Ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ibi ìdáná pẹpẹ náà dọ́gba, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá (12), fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá (12).+ 17 Ìgbásẹ̀ tó yí ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ká jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá (14) ní gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá (14); etí rẹ̀ yí ká jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yí ká.
“Àtẹ̀gùn rẹ̀ dojú kọ ìlà oòrùn.”
18 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Àwọn ìtọ́ni tí wọ́n á máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ti ṣe pẹpẹ nìyí, kí wọ́n lè máa fi odindi ẹbọ sísun rúbọ lórí rẹ̀, kí wọ́n sì lè máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ sórí rẹ̀.’+
19 “‘Kí o fún àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Sádókù+ ní akọ ọmọ màlúù kan látinú agbo ẹran láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ àwọn ló ń wá síwájú mi láti ṣiṣẹ́ fún mi,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 20 ‘Kí o mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì fi í sára ìwo pẹpẹ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sára igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìgbásẹ̀ tó yí i ká àti sí etí rẹ̀ yí ká, láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti láti ṣe ètùtù fún un.+ 21 Kí o wá mú akọ ọmọ màlúù náà tó jẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o lè lọ sun ún níbi tí wọ́n ti ṣètò sílẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì náà, ní ìta ibi mímọ́.+ 22 Ní ọjọ́ kejì, wàá fi òbúkọ kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; wọ́n á sì wẹ pẹpẹ náà mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ bí wọ́n ṣe fi akọ ọmọ màlúù náà wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.’
23 “‘Tí o bá ti wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tán, kí o mú akọ ọmọ màlúù kan látinú agbo ẹran, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá àti àgbò kan látinú ọ̀wọ́ ẹran, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, kí o sì fi wọ́n rúbọ. 24 Kí o gbé wọn wá síwájú Jèhófà, kí àwọn àlùfáà da iyọ̀ sí wọn lára,+ kí wọ́n sì fi wọ́n rú odindi ẹbọ sísun sí Jèhófà. 25 Ojoojúmọ́ ni wàá máa fi òbúkọ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ọjọ́ méje,+ bẹ́ẹ̀ náà ni akọ ọmọ màlúù kan látinú agbo ẹran àti àgbò kan látinú ọ̀wọ́ ẹran; àwọn ẹran tí kò ní àbààwọ́n* ni kí o fi rúbọ. 26 Ọjọ́ méje ni kí wọ́n fi ṣe ètùtù pẹpẹ náà, kí wọ́n wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí wọ́n sì ṣètò rẹ̀ sílẹ̀. 27 Tí àwọn ọjọ́ náà bá pé, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹjọ+ síwájú, àwọn àlùfáà yóò rú àwọn odindi ẹbọ sísun yín* àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ yín lórí pẹpẹ; inú mi yóò sì dùn sí yín,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
44 Ó mú mi pa dà wá sí ẹnubodè ibi mímọ́ tó wà níta tó dojú kọ ìlà oòrùn,+ ó sì wà ní títì pa.+ 2 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Ẹnubodè yìí yóò wà ní títì pa. Wọn ò ní ṣí i, èèyàn kankan ò sì ní gba ibẹ̀ wọlé; torí Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti gba ibẹ̀ wọlé,+ torí náà, yóò wà ní títì pa. 3 Àmọ́, ìjòyè yóò jókòó síbẹ̀ kó lè jẹ oúnjẹ níwájú Jèhófà,+ torí ìjòyè ni. Yóò gba ibi àbáwọlé* ẹnubodè náà wọlé, ibẹ̀ sì ni yóò gbà jáde.”+
4 Lẹ́yìn náà, ó mú mi gba ẹnubodè àríwá wá sí iwájú tẹ́ńpìlì náà. Nígbà tí mo wò, mo rí i pé ògo Jèhófà kún inú tẹ́ńpìlì Jèhófà.+ Torí náà, mo dojú bolẹ̀.+ 5 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, fiyè sílẹ̀,* la ojú rẹ sílẹ̀, kí o sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí gbogbo ohun tí mo bá sọ fún ọ nípa àwọn ìlànà àti òfin tẹ́ńpìlì Jèhófà. Fiyè sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé tẹ́ńpìlì náà dáadáa àti gbogbo ọ̀nà àbájáde ibi mímọ́.+ 6 Kí o sọ fún ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ìwà ìríra tí ẹ̀ ń hù tó gẹ́ẹ́, ilé Ísírẹ́lì. 7 Tí ẹ bá mú àwọn àjèjì tí kò kọlà* ọkàn àti ara wá sínú ibi mímọ́ mi, ṣe ni wọ́n ń sọ tẹ́ńpìlì mi di aláìmọ́. Ẹ̀ ń gbé oúnjẹ, ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀ wá fún mi, àmọ́ torí ìwà ìríra yín, ẹ̀ ń da májẹ̀mú mi. 8 Ẹ ò bójú tó àwọn ohun mímọ́ mi.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń yan àwọn ẹlòmíì pé kí wọ́n bójú tó iṣẹ́ nínú ibi mímọ́ mi.”’
9 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Àjèjì kankan tó ń gbé ní Ísírẹ́lì, tí kò kọlà* ọkàn àti ara kò gbọ́dọ̀ wọnú ibi mímọ́ mi.”’
10 “‘Àmọ́ àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n kúrò lẹ́yìn mi+ nígbà tí Ísírẹ́lì fi mí sílẹ̀ kí wọ́n lè tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* wọn yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 11 Wọ́n á di ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ mi kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn ẹnubodè tẹ́ńpìlì,+ kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì. Wọn yóò pa ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rú odindi ẹbọ sísun àti ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ torí àwọn èèyàn, wọn yóò sì dúró níwájú àwọn èèyàn náà kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ fún wọn. 12 Torí pé iwájú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn ni àwọn ọmọ Léfì náà ti ṣiṣẹ́ fún wọn, tí wọ́n sì di ohun ìkọ̀sẹ̀ tó mú kí ilé Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀,+ ìdí nìyẹn tí mo fi gbé ọwọ́ mi sókè sí wọn tí mo sì búra, wọ́n á sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 13 ‘Wọn ò ní wá sọ́dọ̀ mi láti ṣe àlùfáà mi, wọn ò ní sún mọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ohun mímọ́ jù lọ, ojú á sì tì wọ́n torí ohun ìríra tí wọ́n ṣe. 14 Àmọ́ èmi yóò mú kí wọ́n máa bójú tó àwọn iṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì, màá mú kí wọ́n máa bójú tó ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ àti gbogbo nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe nínú rẹ̀.’+
15 “‘Ní ti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àwọn ọmọ Sádókù,+ àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi mí sílẹ̀,+ wọn yóò wá sọ́dọ̀ mi kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ fún mi, wọn yóò sì dúró níwájú mi kí wọ́n lè fi ọ̀rá+ àti ẹ̀jẹ̀ rúbọ sí mi,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 16 ‘Àwọn ni yóò wọnú ibi mímọ́ mi, wọ́n á wá síbi tábìlì mi kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ fún mi,+ wọ́n á sì bójú tó iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n ṣe fún mi.+
17 “‘Tí wọ́n bá wá sí àwọn ẹnubodè àgbàlá inú, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀.*+ Wọn ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ kankan tí wọ́n fi irun àgùntàn ṣe nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ẹnubodè àgbàlá inú tàbí tí wọ́n bá wọlé. 18 Kí wọ́n wé láwàní tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe sórí, kí wọ́n sì wọ ṣòkòtò péńpé tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe tó máa bo ìbàdí wọn.+ Wọn kò gbọ́dọ̀ wọ ohunkóhun tó máa jẹ́ kí wọ́n làágùn. 19 Kí wọ́n tó jáde lọ sí àgbàlá ìta, ní àgbàlá ìta tí àwọn èèyàn wà, kí wọ́n bọ́ aṣọ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́,+ kí wọ́n sì kó wọn sínú àwọn yàrá ìjẹun mímọ́.*+ Kí wọ́n wá wọ aṣọ míì, kí wọ́n má bàa fi aṣọ wọn sọ àwọn èèyàn di mímọ́. 20 Wọn ò gbọ́dọ̀ fá orí wọn,+ wọn ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí irun orí wọn gùn jù. Kí wọ́n máa gé irun orí wọn lọ sílẹ̀. 21 Àwọn àlùfáà kò gbọ́dọ̀ mu wáìnì tí wọ́n bá wá sí àgbàlá inú.+ 22 Wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ opó tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀;+ àmọ́ wọ́n lè fẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ wúńdíá tàbí ìyàwó àlùfáà tó ti di opó.’+
23 “‘Kí wọ́n fún àwọn èèyàn mi ní ìtọ́ni nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó mọ́ àti ohun yẹpẹrẹ; wọ́n á sì kọ́ wọn ní ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tó mọ́.+ 24 Tí ẹjọ́ kan bá wáyé, àwọn ni kí wọ́n ṣe adájọ́;+ ẹjọ́ tí wọ́n bá dá gbọ́dọ̀ bá àwọn ìdájọ́ mi mu.+ Kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà mi tó wà fún gbogbo àwọn àjọ̀dún mi,+ kí wọ́n sì máa sọ àwọn sábáàtì mi di mímọ́. 25 Wọn ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ òkú èèyàn, torí yóò mú kí wọ́n di aláìmọ́. Àmọ́ wọ́n lè di aláìmọ́ torí bàbá wọn, ìyá wọn, ọmọ wọn ọkùnrin tàbí ọmọ wọn obìnrin, torí arákùnrin wọn tàbí arábìnrin wọn tí kò tíì ní ọkọ.+ 26 Lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti wẹ àlùfáà kan mọ́, kí wọ́n jẹ́ kó dúró fún ọjọ́ méje. 27 Ní ọjọ́ tó bá wọnú ibi mímọ́, tó wá sí àgbàlá inú láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, kó rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
28 “‘Èyí ni yóò jẹ́ ogún wọn: Èmi ni ogún wọn.+ Ẹ má ṣe fún wọn ní ohun ìní kankan ní Ísírẹ́lì, torí èmi ni ohun ìní wọn. 29 Àwọn ni yóò máa jẹ ọrẹ ọkà,+ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi,+ gbogbo ohun tí wọ́n bá sì yà sọ́tọ̀ ní Ísírẹ́lì yóò di tiwọn.+ 30 Èyí tó dáa jù nínú gbogbo àkọ́so èso àti onírúurú ọrẹ tí ẹ bá mú wá yóò di ti àwọn àlùfáà.+ Kí ẹ fún àlùfáà ní àkọ́so ọkà yín tí ẹ ò lọ̀ kúnná.+ Èyí máa mú kí ìbùkún wà lórí ilé yín.+ 31 Àwọn àlùfáà kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹyẹ tàbí ẹran kankan tó ti kú tàbí èyí tí ẹranko fà ya.’+
45 “‘Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà bí ogún,+ kí ẹ mú ìpín kan tó jẹ́ mímọ́ lára ilẹ̀ náà wá fún Jèhófà láti fi ṣe ọrẹ.+ Kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́,* kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́.+ Gbogbo agbègbè* rẹ̀ yóò jẹ́ mímọ́. 2 Apá kan nínú ilẹ̀ náà tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba yóò wà fún ibi mímọ́, ìwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìgbọ̀nwọ́ níbùú àti lóòró,+ yóò sì ní ibi ìjẹko lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́.+ 3 Látinú ibi tí ẹ wọ̀n yìí ni kí ẹ ti wọn ibi tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́, inú rẹ̀ ni ibi mímọ́ yóò wà, ohun mímọ́ jù lọ. 4 Ibẹ̀ ló máa jẹ́ ibi mímọ́ nínú ilẹ̀ náà, yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà,+ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, tó ń wá síwájú Jèhófà láti ṣiṣẹ́ fún un.+ Ibẹ̀ ni ilé wọn máa wà, ibẹ̀ ló sì máa jẹ́ ibi mímọ́ fún tẹ́ńpìlì náà.
5 “‘Àwọn ọmọ Léfì, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì máa ní ibì kan tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́,+ ogún (20) yàrá ìjẹun*+ yóò sì jẹ́ ohun ìní wọn.
6 “‘Ẹ ó ya apá kan sọ́tọ̀ tó máa jẹ́ ohun ìní tó jẹ́ ti ìlú. Gígùn rẹ̀ máa jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, (èyí tó bá ilẹ̀ mímọ́ náà mu) fífẹ̀ rẹ̀ á sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ìgbọ̀nwọ́.+ Yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì.
7 “‘Ní ti ìjòyè, ilẹ̀ rẹ̀ yóò wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ilẹ̀ mímọ́ náà àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ tó jẹ́ ti ìlú. Yóò wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà àti ilẹ̀ tó jẹ́ ti ìlú náà. Apá ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn ló máa wà. Gígùn rẹ̀ láti ààlà ìwọ̀ oòrùn dé ààlà ìlà oòrùn yóò dọ́gba pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn ilẹ̀ tí ẹ̀yà kan ní.+ 8 Ilẹ̀ yìí yóò di ohun ìní rẹ̀ ní Ísírẹ́lì. Àwọn ìjòyè mi kò ní ni àwọn èèyàn mi lára mọ́,+ wọ́n á sì fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní ilé Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ náà bí wọ́n bá ṣe rí.’+
9 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ìjòyè Ísírẹ́lì!’
“‘Ẹ má hùwà ipá mọ́, ẹ má sì ni àwọn èèyàn lára mọ́. Ẹ ṣe ohun tó tọ́, tó sì jẹ́ òdodo.+ Ẹ má gba ohun ìní àwọn èèyàn mi mọ́,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 10 ‘Àwọn òṣùwọ̀n tó péye ni kí ẹ máa lò, kí ẹ sì máa lo òṣùwọ̀n eéfà* àti òṣùwọ̀n báàtì* tó péye.+ 11 Kí ìwọ̀n pàtó kan wà tí a ó máa lò fún òṣùwọ̀n eéfà àti báàtì. Kí ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n hómérì* kún òṣùwọ̀n báàtì, kí ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n hómérì sì kún òṣùwọ̀n eéfà. Òṣùwọ̀n hómérì ni kí ẹ máa lò láti fi díwọ̀n. 12 Kí ṣékélì*+ kan jẹ́ ogún (20) gérà.* Àpapọ̀ ogún (20) ṣékélì àti ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) àti ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ni kó jẹ́ mánẹ̀* kan tí ẹ ó máa lò.’
13 “‘Ọrẹ tí ẹ máa mú wá nìyí: àlìkámà* tó kún ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n eéfà ni kí ẹ mú látinú òṣùwọ̀n hómérì kọ̀ọ̀kan àti ọkà bálì tó kún ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n eéfà ni kí ẹ mú látinú òṣùwọ̀n hómérì kọ̀ọ̀kan. 14 Òṣùwọ̀n báàtì ni kí ẹ máa fi díwọ̀n òróró. Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* ni báàtì jẹ́. Òṣùwọ̀n báàtì mẹ́wàá ló wà nínú òṣùwọ̀n hómérì kan, torí báàtì mẹ́wàá ni hómérì kan. 15 Kí ẹ sì mú àgùntàn kọ̀ọ̀kan nínú igba (200) àgùntàn látinú agbo ẹran ọ̀sìn Ísírẹ́lì wá bí ọrẹ. Ìwọ̀nyí ni wọ́n á lò fún ọrẹ ọkà,+ odindi ẹbọ sísun+ àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ kí wọ́n lè ṣe ètùtù fún àwọn èèyàn náà,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
16 “‘Gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà yóò mú ọrẹ yìí wá+ fún ìjòyè ní Ísírẹ́lì. 17 Àmọ́ ìjòyè náà ló máa mú odindi ẹbọ sísun,+ ọrẹ ọkà+ àti ọrẹ ohun mímu wá nígbà àwọn àjọ̀dún,+ ọjọ́ òṣùpá tuntun, àwọn Sábáàtì+ àti ní gbogbo àjọ̀dún tí ilé Ísírẹ́lì máa ń ṣe.+ Òun ló máa pèsè ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ọkà, odindi ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀, láti ṣe ètùtù torí ilé Ísírẹ́lì.’
18 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kìíní, kí o mú akọ ọmọ màlúù kan látinú agbo ẹran, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, kí o sì wẹ ibi mímọ́ náà mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.+ 19 Àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yóò sì fi sára férémù ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì náà,+ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìgbásẹ̀ tó yí pẹpẹ náà ká àti sára férémù ilẹ̀kùn ẹnubodè àgbàlá inú. 20 Ohun tí ẹ máa ṣe ní ọjọ́ keje oṣù náà nìyẹn, torí ẹnikẹ́ni tó bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀ tàbí tó dẹ́ṣẹ̀ láìmọ̀;+ kí ẹ sì ṣe ètùtù láti sọ tẹ́ńpìlì náà di mímọ́.+
21 “‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní, kí ẹ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá.+ Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú.+ 22 Ní ọjọ́ yẹn, ìjòyè náà yóò pèsè akọ ọmọ màlúù láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ torí ara rẹ̀ àti torí gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà.+ 23 Yóò pèsè akọ ọmọ màlúù méje àti àgbò méje tí ara wọn dá ṣáṣá lójoojúmọ́ fún ọjọ́ méje tí wọ́n á fi ṣe àjọyọ̀ náà.+ Wọ́n á jẹ́ odindi ẹbọ sísun sí Jèhófà, yóò sì tún máa pèsè òbúkọ kan lójoojúmọ́ láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 24 Yóò tún pèsè òṣùwọ̀n eéfà kan fún akọ ọmọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, yóò sì tún pèsè òróró tó kún òṣùwọ̀n hínì* kan fún òṣùwọ̀n eéfà kọ̀ọ̀kan.
25 “‘Ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje, kó pèsè ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, odindi ẹbọ sísun, ọrẹ ọkà àti òróró kan náà fún ọjọ́ méje tí wọ́n á fi ṣe àjọyọ̀ náà.’”+
46 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Kí ẹnubodè àgbàlá inú tó dojú kọ ìlà oòrùn+ wà ní títì pa+ fún ọjọ́ mẹ́fà tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́,+ àmọ́ kí wọ́n ṣí i ní ọjọ́ Sábáàtì àti ọjọ́ òṣùpá tuntun. 2 Ìjòyè náà máa gba ibi àbáwọlé*+ ẹnubodè náà wọlé láti ìta, yóò sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn ẹnubodè náà. Àwọn àlùfáà yóò rú odindi ẹbọ sísun rẹ̀ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀, yóò sì tẹrí ba níbi ẹnubodè náà, yóò wá jáde. Àmọ́ kí wọ́n má ti ẹnubodè ibẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. 3 Àwọn èèyàn ilẹ̀ náà yóò tún tẹrí ba níwájú Jèhófà ní ibi ẹnubodè yẹn ní àwọn ọjọ́ Sábáàtì àti àwọn ọjọ́ òṣùpá tuntun.+
4 “‘Kí odindi ẹbọ sísun tí ìjòyè náà máa mú wá fún Jèhófà ní ọjọ́ Sábáàtì jẹ́ akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́fà àti àgbò kan tí ara wọn dá ṣáṣá.+ 5 Ọrẹ ọkà yóò jẹ́ òṣùwọ̀n eéfà* kan fún àgbò àti ohunkóhun tó bá lè mú wá fún àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn pẹ̀lú òróró tó kún òṣùwọ̀n hínì* kan àti òṣùwọ̀n eéfà kọ̀ọ̀kan.+ 6 Ní ọjọ́ òṣùpá tuntun, ọrẹ náà yóò jẹ́ akọ ọmọ màlúù kan nínú agbo ẹran, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́fà àti àgbò kan; kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá.+ 7 Kí ọrẹ ọkà tó máa mú wá jẹ́ òṣùwọ̀n eéfà kan fún akọ ọmọ màlúù kan, òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò àti ohunkóhun tí agbára rẹ̀ bá ká fún àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn. Kó sì mú òróró tó kún òṣùwọ̀n hínì kan wá fún òṣùwọ̀n eéfà kọ̀ọ̀kan.
8 “‘Tí ìjòyè náà bá fẹ́ wọlé, kó gba ibi àbáwọlé* ẹnubodè náà wọlé, ibẹ̀ náà ni kó sì gbà jáde.+ 9 Tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá sì wá síwájú Jèhófà nígbà àjọ̀dún,+ kí àwọn tó bá gba ẹnubodè àríwá+ wọlé láti jọ́sìn gba ẹnubodè gúúsù+ jáde, kí àwọn tó bá sì gba ẹnubodè gúúsù wọlé gba ẹnubodè àríwá jáde. Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ gba ẹnubodè tó gbà wọlé jáde, ẹnubodè tó kọjú sí wọn ni kí wọ́n gbà jáde. 10 Ní ti ìjòyè tó wà láàárín wọn, nígbà tí wọ́n bá wọlé ni kó wọlé, nígbà tí wọ́n bá sì jáde ni kó jáde. 11 Nígbà àwọn àjọyọ̀ àti àjọ̀dún, kí ọrẹ ọkà jẹ́ òṣùwọ̀n eéfà kan fún akọ ọmọ màlúù, òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò àti ohunkóhun tó bá lè mú wá fún àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, kí ó mú òróró tó kún òṣùwọ̀n hínì kan wá fún òṣùwọ̀n eéfà kọ̀ọ̀kan.+
12 “‘Tí ìjòyè náà bá pèsè odindi ẹbọ sísun+ tàbí ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tó fi ṣe ọrẹ àtinúwá sí Jèhófà, kí wọ́n ṣí ẹnubodè tó dojú kọ ìlà oòrùn fún un, kó sì pèsè odindi ẹbọ sísun rẹ̀ àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ bó ṣe máa ń ṣe ní ọjọ́ Sábáàtì.+ Tó bá sì ti jáde, kí wọ́n ti ẹnubodè náà.+
13 “‘Lójoojúmọ́, máa pèsè akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá láti fi ṣe odindi ẹbọ sísun sí Jèhófà.+ Àràárọ̀ ni kí o máa ṣe é. 14 Ní àràárọ̀, kí o tún máa pèsè ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n eéfà láti fi ṣe ọrẹ ọkà, pẹ̀lú òróró tó kún ìdá mẹ́ta òṣùwọ̀n hínì láti fi wọ́n ìyẹ̀fun tó kúnná bí ọrẹ ọkà tí ẹ ó máa mú wá fún Jèhófà déédéé. Bó ṣe máa rí títí lọ nìyí. 15 Kí wọ́n máa pèsè akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, ọrẹ ọkà àti òróró ní àràárọ̀ láti fi ṣe odindi ẹbọ sísun déédéé.’
16 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Tí ìjòyè náà bá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀bùn láti fi ṣe ogún, yóò di ohun ìní àwọn ọmọ rẹ̀. Ohun ìní tí wọ́n jogún ni. 17 Àmọ́ tó bá mú lára ogún rẹ̀ tó sì fi ṣe ẹ̀bùn fún ọ̀kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀; ó máa jẹ́ ti ìránṣẹ́ náà títí di ọdún òmìnira;+ yóò wá pa dà di ti ìjòyè náà. Àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan ló lè jogún ohun ìní rẹ̀ títí láé. 18 Ìjòyè náà kò gbọ́dọ̀ fipá gba ohun ìní kankan tó jẹ́ ogún àwọn èèyàn náà. Inú nǹkan ìní tirẹ̀ ni kó ti fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ogún, kí wọ́n má bàa lé ìkankan nínú àwọn èèyàn mi kúrò nídìí ohun ìní wọn.’”
19 Ó wá mú mi gba ọ̀nà àbáwọlé+ tó dojú kọ àríwá,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè tó lọ sí àwọn yàrá ìjẹun mímọ́* tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà, mo sì rí ibì kan lẹ́yìn rẹ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn. 20 Ó sọ fún mi pé: “Ibí ni àwọn àlùfáà yóò ti máa se ẹbọ ẹ̀bi àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n á sì ti máa yan ọrẹ ọkà,+ kí wọ́n má bàa gbé ohunkóhun jáde lọ sí àgbàlá ìta, kí wọ́n sì sọ àwọn èèyàn náà di mímọ́.”+
21 Ó mú mi jáde wá sí àgbàlá ìta, ó mú mi gba igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbàlá náà, mo sì rí àgbàlá kan ní igun kọ̀ọ̀kan àgbàlá ìta. 22 Àgbàlá kéékèèké wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbàlá náà, gígùn wọn jẹ́ ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́,* fífẹ̀ wọn sì jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́. Ìwọ̀n mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba.* 23 Ògiri àgbàlá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ìgbásẹ̀ yí ká, ìsàlẹ̀ ìgbásẹ̀ àwọn ògiri náà sì ni ibi tí wọ́n ti ń se àwọn ohun tí wọ́n mú wá bí ọrẹ. 24 Ó wá sọ fún mi pé: “Àwọn ilé yìí ni àwọn ìránṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì ti ń se ohun tí àwọn èèyàn mú wá láti fi rúbọ.”+
47 Lẹ́yìn náà, ó mú mi pa dà wá sí ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì náà,+ mo sì rí omi tó ń ṣàn lọ sí ìlà oòrùn láti abẹ́ ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì náà,+ torí iwájú tẹ́ńpìlì náà dojú kọ ìlà oòrùn. Omi náà ń ṣàn wálẹ̀ láti abẹ́ tẹ́ńpìlì náà ní apá ọ̀tún, ní gúúsù pẹpẹ.
2 Ó wá mú mi gba ẹnubodè àríwá jáde,+ ó mú mi lọ síta, ó sì mú mi yí ká ẹnubodè ìta tó dojú kọ ìlà oòrùn,+ mo sì rí i tí omi ń sun láti apá ọ̀tún.
3 Nígbà tí ọkùnrin náà jáde lọ sí apá ìlà oòrùn tó sì mú okùn ìdíwọ̀n dání,+ ó wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́,* ó sì mú mi gba inú omi náà; omi náà dé kókósẹ̀.
4 Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba inú omi náà. Ó dé orúnkún.
Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́, ó mú mi gba inú rẹ̀, omi náà sì dé ìbàdí.
5 Nígbà tó tún wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́, mi ò lè fi ẹsẹ̀ rin omi náà kọjá torí ó kún, ó sì jìn débi pé èèyàn ní láti lúwẹ̀ẹ́ kọjá ni, àní alagbalúgbú omi téèyàn ò lè fi ẹsẹ̀ rìn kọjá ni.
6 Ó bi mí pé: “Ṣé o rí èyí, ọmọ èèyàn?”
Ó wá mú mi rìn pa dà sí etí odò náà. 7 Nígbà tí mo pa dà, mo rí i pé igi pọ̀ gan-an ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì etí odò náà.+ 8 Ó wá sọ fún mi pé: “Omi yìí ń ṣàn lọ sí agbègbè ìlà oòrùn títí lọ dé Árábà,*+ ó sì ń ṣàn wọnú òkun. Tó bá wọnú òkun,+ yóò wo omi ibẹ̀ sàn. 9 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀dá alààyè* yóò máa wà láàyè níbikíbi tí omi* náà bá ṣàn dé. Ẹja máa pọ̀ gan-an níbẹ̀ torí omi yìí máa ṣàn débẹ̀. Yóò wo omi òkun náà sàn, gbogbo ohun tó bá sì wà níbi tí omi náà ṣàn dé yóò máa wà láàyè.
10 “Àwọn apẹja yóò dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ láti Ẹ́ń-gédì+ títí lọ dé Eni-égíláímù, níbi tí wọ́n ń sá àwọ̀n sí. Oríṣiríṣi ẹja yóò pọ̀ gan-an níbẹ̀, bí àwọn ẹja inú Òkun Ńlá.*+
11 “Yóò ní irà àti àbàtà, wọn kò sì ní rí ìwòsàn. Wọ́n á di ilẹ̀ iyọ̀.+
12 “Onírúurú igi tó ń so èso fún jíjẹ yóò hù lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì odò náà. Ewé wọn ò ní rọ; èso wọn ò sì ní tán. Oṣooṣù ni wọ́n á máa so èso tuntun, torí láti ibi mímọ́ ni omi ti ń ṣàn dé ọ̀dọ̀ wọn.+ Èso wọn yóò jẹ́ oúnjẹ, ewé wọn á sì wà fún ìwòsàn.”+
13 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ilẹ̀ tí ẹ máa yàn bí ogún fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá (12) nìyí, Jósẹ́fù yóò sì ní ìpín méjì.+ 14 Ẹ máa jogún rẹ̀, ìpín kálukú yóò sì dọ́gba.* Mo búra pé màá fún àwọn baba ńlá yín ní ilẹ̀ yìí,+ mo sì ti pín in fún yín* láti jẹ́ ogún yín ní báyìí.
15 “Ààlà ilẹ̀ náà ní apá àríwá nìyí: Ó lọ láti Òkun Ńlá títí lọ dé Hẹ́tílónì,+ sí ọ̀nà Sédádì,+ 16 Hámátì,+ Bérótà+ àti Síbúráímù, tó wà láàárín agbègbè Damásíkù àti Hámátì, ó dé Haseri-hátíkónì, tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà Háúránì.+ 17 Ààlà náà yóò jẹ́ láti òkun dé Hasari-énónì,+ lẹ́bàá ààlà Damásíkù sí àríwá àti ààlà Hámátì.+ Ààlà tó wà ní àríwá nìyí.
18 “Ààlà tó wà ní ìlà oòrùn gba àárín Háúránì àti Damásíkù, títí lọ dé ẹ̀gbẹ́ Jọ́dánì láàárín Gílíádì+ àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Kí ẹ wọ̀n ọ́n láti ibi tí ààlà wà dé òkun ìlà oòrùn.* Ààlà tó wà ní ìlà oòrùn nìyí.
19 “Ààlà tó wà ní gúúsù* yóò jẹ́ láti Támárì dé omi Mẹriba-kádéṣì,+ yóò dé Àfonífojì* àti Òkun Ńlá.+ Ààlà tó wà ní gúúsù* nìyí.
20 “Òkun Ńlá ló wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, láti ibi tí ààlà wà dé ibì kan tó wà ní òdìkejì Lebo-hámátì.*+ Ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn nìyí.”
21 “Kí ẹ pín ilẹ̀ yìí láàárín ara yín, láàárín ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì. 22 Kí ẹ pín in kó jẹ́ ogún láàárín ara yín àti láàárín àwọn àjèjì tó ń gbé pẹ̀lú yín tí wọ́n sì ti bímọ nígbà tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú yín; bí ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n á jẹ́ sí yín. Àwọn náà yóò rí ogún gbà bíi tiyín láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì. 23 Agbègbè tó jẹ́ ti ẹ̀yà tí àjèjì náà ń gbé ni kí ẹ ti fún un ní ogún,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
48 “Orúkọ àwọn ẹ̀yà náà nìyí, bẹ̀rẹ̀ láti ìkángun àríwá: ìpín Dánì+ wà lẹ́bàá ọ̀nà Hẹ́tílónì lọ dé Lebo-hámátì*+ dé Hasari-énánì, lẹ́bàá ààlà Damásíkù sí apá àríwá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Hámátì;+ ó bẹ̀rẹ̀ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn títí dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 2 Ìpín Áṣérì+ bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Dánì, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 3 Ìpín Náfútálì+ bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Áṣérì, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 4 Ìpín Mánásè+ bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Náfútálì, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 5 Ìpín Éfúrémù bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Mánásè,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 6 Ìpín Rúbẹ́nì bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Éfúrémù,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 7 Ìpín Júdà bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Rúbẹ́nì,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 8 Bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Júdà, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn, kí fífẹ̀ ilẹ̀ tí ẹ ó yà sọ́tọ̀ láti fi ṣe ọrẹ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́,*+ kí gígùn rẹ̀ sì dọ́gba pẹ̀lú ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà yòókù láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. Àárín rẹ̀ ni ibi mímọ́ máa wà.
9 “Kí ilẹ̀ tí ẹ ó yà sọ́tọ̀ láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́. 10 Èyí ló máa jẹ́ ilẹ̀ mímọ́ tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà.+ Yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá àríwá, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá ìwọ̀ oòrùn, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá ìlà oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá gúúsù. Ibi mímọ́ Jèhófà yóò wà ní àárín rẹ̀. 11 Yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Sádókù+ tí wọ́n ti sọ di mímọ́, àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n ṣe fún mi, tí wọn ò sì fi mí sílẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Léfì fi mí sílẹ̀.+ 12 Wọn yóò ní ìpín lára ilẹ̀ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ, ní ààlà àwọn ọmọ Léfì.
13 “Nítòsí ilẹ̀ àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì yóò ní ilẹ̀ kan tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́. (Gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ìgbọ̀nwọ́.) 14 Wọn ò gbọ́dọ̀ ta èyíkéyìí lára ibi tó dáa jù nínú ilẹ̀ náà tàbí kí wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fún ẹlòmíì torí ohun mímọ́ ló jẹ́ fún Jèhófà.
15 “Ibi tó ṣẹ́ kù jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, lẹ́bàá ààlà tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́. Ó máa jẹ́ ti gbogbo ìlú,+ wọ́n á máa gbé ibẹ̀, ẹran wọn á sì máa jẹko níbẹ̀. Ìlú náà yóò wà ní àárín rẹ̀.+ 16 Ìwọ̀n ìlú náà nìyí: Ààlà tó wà ní àríwá jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ti gúúsù jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ti ìlà oòrùn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ti ìwọ̀ oòrùn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́. 17 Ibi ìjẹko ìlú náà yóò jẹ́ igba ó lé àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ sí apá àríwá, igba ó lé àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ sí apá gúúsù, igba ó lé àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ sí apá ìlà oòrùn àti igba ó lé àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ sí apá ìwọ̀ oòrùn.
18 “Gígùn ilẹ̀ tó ṣẹ́ kù yóò dọ́gba pẹ̀lú ilẹ̀ mímọ́,+ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ sí apá ìlà oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ sí apá ìwọ̀ oòrùn. Yóò dọ́gba pẹ̀lú ilẹ̀ mímọ́ náà, èso rẹ̀ ni àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ìlú náà yóò sì máa jẹ. 19 Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ nínú ìlú náà yóò máa dá oko níbẹ̀.+
20 “Gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n fi ṣe ọrẹ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Kí ẹ yà á sọ́tọ̀ láti jẹ́ ilẹ̀ mímọ́ pẹ̀lú ohun ìní ìlú náà.
21 “Ohun tó bá ṣẹ́ kù lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ilẹ̀ mímọ́ náà àti ohun ìní ìlú náà yóò jẹ́ ti ìjòyè.+ Yóò wà lẹ́bàá àwọn ààlà tó wà ní apá ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ mímọ́ náà, tí gígùn wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́. Yóò dọ́gba pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ tí wọ́n jọ pààlà, yóò sì jẹ́ ti ìjòyè. Àárín rẹ̀ ni ilẹ̀ mímọ́ náà àti ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì náà yóò wà.
22 “Ohun ìní àwọn ọmọ Léfì àti ohun ìní ìlú náà yóò wà láàárín ohun tó jẹ́ ti ìjòyè. Ilẹ̀ ìjòyè náà yóò wà láàárín ààlà Júdà+ àti ààlà Bẹ́ńjámínì.
23 “Ní ti àwọn ẹ̀yà tó ṣẹ́ kù, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ni ìpín Bẹ́ńjámínì.+ 24 Ìpín Síméónì bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Bẹ́ńjámínì,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 25 Ìpín Ísákà+ bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Síméónì, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 26 Ìpín Sébúlúnì bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Ísákà,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn.+ 27 Ìpín Gádì bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Sébúlúnì,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 28 Ààlà tó wà ní gúúsù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà Gádì, yóò jẹ́ láti Támárì+ dé omi Mẹriba-kádéṣì,+ dé Àfonífojì,*+ títí dé Òkun Ńlá.*
29 “Ilẹ̀ yìí ni ogún tí ẹ máa pín fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì,+ ìwọ̀nyí sì ni ìpín wọn,”+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
30 “Àwọn ibi tí wọ́n á máa gbà jáde nínú ìlú náà nìyí: Apá àríwá yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́.+
31 “Orúkọ àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni wọ́n á máa pe àwọn ẹnubodè ìlú náà. Ẹnubodè mẹ́ta yóò wà ní àríwá, ọ̀kan jẹ́ ti Rúbẹ́nì, ọ̀kan jẹ́ ti Júdà, ọ̀kan sì jẹ́ ti Léfì.
32 “Apá ìlà oòrùn yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ẹnubodè mẹ́ta ló sì wà níbẹ̀: ọ̀kan jẹ́ ti Jósẹ́fù, ọ̀kan jẹ́ ti Bẹ́ńjámínì, ọ̀kan sì jẹ́ ti Dánì.
33 “Apá gúúsù yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ẹnubodè mẹ́ta ló sì wà níbẹ̀: ọ̀kan jẹ́ ti Síméónì, ọ̀kan jẹ́ ti Ísákà, ọ̀kan sì jẹ́ ti Sébúlúnì.
34 “Apá ìwọ̀ oòrùn yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ẹnubodè mẹ́ta ló sì wà níbẹ̀: ọ̀kan jẹ́ ti Gádì, ọ̀kan jẹ́ ti Áṣérì, ọ̀kan sì jẹ́ ti Náfútálì.
35 “Ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) ìgbọ̀nwọ́ ni yóò jẹ́ yí ká. Láti ọjọ́ yẹn lọ, orúkọ ìlú náà yóò máa jẹ́ Jèhófà Wà Níbẹ̀.”+
Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Ló Ń Fúnni Lókun.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “mànàmáná.”
Ó ṣeé ṣe kí wọ́n dábùú ara wọn ní àárín méjì.
Ní Héb., “ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè náà.”
Tàbí kó jẹ́, “ìyẹ́ wọn rí gbọọrọ.”
“Ọmọ èèyàn”; èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbà 93 tí ọ̀rọ̀ yìí fara hàn nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì.
Tàbí “olórí kunkun.”
Tàbí kó jẹ́, “bó tilẹ̀ jẹ́ pé alágídí làwọn èèyàn náà tí wọ́n sì dà bí ohun tó ń gún ọ.”
Tàbí “Orin ọ̀fọ̀.”
Ní Héb., “jẹ ohun tí o rí.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ èèyàn rẹ.”
Tàbí “ọrùn rẹ ni màá ka ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “tí kò sì ṣe òdodo mọ́.”
Tàbí “ọrùn rẹ ni màá ka ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “rù ú,” ìyẹn, kí Ìsíkíẹ́lì fi ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀ rù ú.
Tàbí “wíìtì.”
Nǹkan bíi 230 gíráàmù. Wo Àfikún B14.
Nǹkan bíi Lítà 0.6. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “èèwọ̀.”
Ní Héb., “èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá búrẹ́dì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì.
Ní Héb., “sínú gbogbo afẹ́fẹ́.”
Tàbí “dín yín kù.”
Tàbí “àìsàn.”
Ní Héb., “sínú gbogbo afẹ́fẹ́.”
Ní Héb., “èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá búrẹ́dì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì.
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Tàbí “oníṣekúṣe; aṣẹ́wó.”
Tàbí “mú kí wọ́n bá àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn ṣèṣekúṣe.”
Tàbí “ẹbọ tí òórùn rẹ̀ ń tuni lára.”
Ní Héb., “jí.”
Tàbí kó jẹ́, “Òdòdó ẹ̀yẹ.”
Tàbí kó jẹ́, “Òdòdó ẹ̀yẹ.”
Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”
Ìyẹn ni pé, àwọn tó ń rà àti àwọn tó ń tà kò ní rí àǹfààní kankan, torí gbogbo wọn ló máa pa run.
Tàbí kó jẹ́, “torí àṣìṣe rẹ̀.”
Ìyẹn ni pé, ìbẹ̀rù á mú kí wọ́n máa tọ̀ sára.
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Ní Héb., “jìnnìjìnnì sì bò wọ́n.”
Ìyẹn ni pé, wọ́n á fá orí wọn torí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀.
Tàbí “ọkàn wọn.”
Ìyẹn, fàdákà àti wúrà wọn.
Ìyẹn, àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà wọn ṣe.
Ìyẹn, wúrà àti fàdákà wọn tí wọ́n fi ṣe ère.
Ó jọ pé ibi mímọ́ Jèhófà ní inú lọ́hùn-ún ló ń sọ.
Ìyẹn, ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n á fi kó wọn lẹ́rú.
Tàbí “ìtọ́ni.”
Tàbí “ìrẹ̀wẹ̀sì.”
Ní Héb., “àmì.”
Ní Héb., “àmì.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Tàbí “tí ó to.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Ó jọ pé ẹ̀ka tí wọ́n fi ń bọ̀rìṣà ni.
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ibi tí akọ̀wé ń rọ yíǹkì sí.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ìyẹn, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kérúbù náà.
Ní Héb., “òun ni ẹ̀dá alààyè.”
Ní Héb., “ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè náà.”
Ní Héb., “Èyí ni ẹ̀dá alààyè náà.”
Tàbí “lòdì sí.”
Ní Héb., “Òun,” ìyẹn Jerúsálẹ́mù, níbi tí àwọn Júù rò pé àwọn ti máa rí ààbò.
Tàbí “ìkòkò ìsebẹ̀ ẹlẹ́nu fífẹ̀.”
Tàbí “ohun tó wá sí yín lẹ́mìí.”
Ní Héb., “kí wọ́n ní ọkàn kan.”
Ìyẹn, ọkàn tó ń jẹ́ kí Ọlọ́run darí òun.
Ní Héb., “ilé.”
Tàbí “tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ látinú ọkàn wọn.”
Ìyẹn ni pé, wọ́n máa ń fi ẹfun kun àwọn ògiri inú tí kò lágbára kó lè dà bíi pé ó lágbára.
Ní Héb., “àti ìwọ yìnyín.”
Ìyẹn, ìfúnpá tàbí ẹ̀gbà àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “àwọn ọkàn.”
Tàbí “àwọn ọkàn.”
Tàbí “àwọn ọkàn.”
Tàbí “ni ín lára.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Ní Héb., “mú ilé Ísírẹ́lì nínú ọkàn wọn.”
Ní Héb., “èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá búrẹ́dì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì.
Tàbí “ọkàn wọn.”
Tàbí “pa wọ́n lọ́mọ jẹ.”
Tàbí “ọkàn wọn.”
Tàbí “ìdájọ́ mi mẹ́rin tó burú jáì.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “etí aṣọ.”
Tàbí “awọ séálì.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “kúnjú ìwọ̀n láti dé ipò ayaba.”
Tàbí “Orúkọ rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri.”
Ìyẹn, àwọn ère ọkùnrin.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “la itan rẹ fún gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ.”
Ní Héb., “àwọn aládùúgbò rẹ ẹlẹ́ran ńlá.”
Tàbí “tí ọkàn wọn fẹ́.”
Ní Héb., “ilẹ̀ Kénáánì.”
Ní Héb., “àìsàn.”
Tàbí kó jẹ́, “Wo bí mo ṣe bínú sí ọ tó.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Ó lè jẹ́ àwọn àrọko rẹ̀ ló ń sọ.
Ní Héb., “lápá òsì rẹ.”
Ní Héb., “lápá ọ̀tún rẹ.”
Tàbí “ti gbèjà àwọn arábìnrin rẹ.”
Ní Héb., “ṣe ètùtù fún ọ.”
Ní Héb., “ilẹ̀ Kénáánì.”
Ní Héb., “èso.”
Ìyẹn, Nebukadinésárì.
Ìyẹn, Sedekáyà.
Tàbí “pa ọ̀pọ̀ ọkàn run.”
Ní Héb., “fi ọwọ́ fúnni.”
Ní Héb., “sínú gbogbo afẹ́fẹ́.”
Tàbí “ẹ̀mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “Ẹni; Èèyàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Ní Héb., “tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.”
Tàbí “Ẹni; Èèyàn.”
Ní Héb., “rántí.”
Tàbí “tí kò sì ṣe òdodo.”
Tàbí “ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “ṣe ọkàn tuntun àti ẹ̀mí tuntun fún ara yín.”
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Tàbí “láàárín àwọn ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí kó jẹ́, “bí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ.”
Tàbí “àwọn ọ̀pá.”
Tàbí “láti kéde ìdájọ́ lé wọn lórí?”
Ní Héb., “gbé ọwọ́ mi sókè.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “ṣe amí rẹ̀.”
Tàbí “tó ní ọ̀ṣọ́.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Ìyẹn, Ísírẹ́lì.
Ìyẹn, Ísírẹ́lì.
Ìyẹn, Ísírẹ́lì.
Tàbí “tó ní ọ̀ṣọ́.”
Ní Héb., “ojú mi.”
Ìyẹn, Ísírẹ́lì.
Ní Héb., “ojú wọn ò kúrò lára.”
Tàbí “tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “ní ẹ̀mí.”
Tàbí “ṣe ìránṣẹ́ fún; sin.”
Ní Héb., “wọnú ìdè.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “ojú.”
Tàbí “èèyàn.”
Tàbí “òwe.”
Tàbí “èèyàn.”
Ní Héb., “ìbàdí rẹ.”
Ìyẹn ni pé, ìbẹ̀rù á mú kí wọ́n máa tọ̀ sára.
Ìyẹn, idà Jèhófà.
Tàbí “Ọ̀pá àṣẹ náà kò.”
Ní Héb., “ọwọ́.”
Ní Héb., “ère téráfímù.”
Ìyẹn, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.
Ní Héb., “ọwọ́.”
Ní Héb., “sí ọrùn àwọn tí wọ́n pa.”
Ní Héb., “ṣé o máa ṣèdájọ́, ṣé o máa ṣèdájọ́.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Tàbí “ọmọ aláìlóbìí.”
Ní Héb., “tú ìhòòhò bàbá wọn síta.”
Tàbí “ń gba èlé gọbọi.”
Ní Héb., “ọkàn.”
Tàbí “àwọn ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ó túmọ̀ sí “Àgọ́ Rẹ̀.”
Ó túmọ̀ sí “Àgọ́ Mi Wà Nínú Rẹ̀.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Tàbí “bá a ṣèṣekúṣe.”
Tàbí “ọkàn rẹ̀.”
Tàbí “tí ọkàn mi.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “àwọn tí wọ́n pè.”
Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.
Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “kẹ̀yìn sí mi.”
Ìyẹn, àgbèrè ẹ̀sìn.
Ní Héb., “orúkọ ọjọ́ náà.”
Tàbí “Fi ìtàn pòwe.”
Tàbí “ìkòkò ìsebẹ̀ ẹlẹ́nu fífẹ̀.”
Tàbí “lu àyà rẹ.”
Tàbí “irunmú.”
Ní Héb., “búrẹ́dì àwọn èèyàn.”
Tàbí “tí ọkàn yín yọ́nú sí.”
Tàbí “wu ọkàn wọn.”
Tàbí “àgọ́ olódi.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.”
Tàbí “lọ́ṣọ̀ọ́.”
Tàbí “Bí àwọn Filísínì ṣe rẹró sínú.”
Ní Héb., “àwọn ọmọbìnrin.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “àwọn èèyàn.”
Tàbí “ẹ̀rọ.”
Tàbí “idà.”
Ní Héb., “àwọn tí wọ́n pa.”
Tàbí “àwọn ìjòyè.”
Tàbí “àwọ̀lékè tí kò lápá.”
Ní Héb., “wọ̀ wọ́n láṣọ.”
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Ní Héb., “Òun àti àwọn.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “lóge.”
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Tàbí “igi óákù.”
Tàbí “Aṣọ àtàtà.”
Ní Héb., “tó ti dàgbà.”
Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.
Tàbí “apata ribiti.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “irun àgùntàn aláwọ̀ eérú tó pọ́n fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.”
Igi yìí ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí igi sínámónì.
Esùsú tó ń ta sánsán.
Tàbí “aṣọ tí wọ́n hun.”
Tàbí kó jẹ́, “o di ológo.”
Ní Héb., “ìjọ.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Ní Héb., “O fi èdìdì di àwòṣe kan.”
Nínú ẹsẹ yìí àti àwọn tó tẹ̀ lé e, “Náílì” ń tọ́ka sí odò yẹn gangan àti àwọn odò tó ṣàn jáde látinú rẹ̀.
Ní Héb., “koríko etí omi.”
Ní Héb., “ìbàdí.”
Ní Héb., “ó ti sọ pé.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ìyẹn, láti gbógun ti Tírè.
Tàbí “láti fún ilé Ísírẹ́lì lókun.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “gbogbo àwọn tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì.”
Ó lè jẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gbára lé Íjíbítì ló tọ́ka sí.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Tàbí “Mémúfísì.”
Tàbí “ọmọ ọba.”
Ìyẹn, Tíbésì.
Tàbí “Mémúfísì.”
Ìyẹn, Heliopólísì.
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “Èmi yóò fi kún agbára ọba Bábílónì.”
Ìyẹn, níwájú ọba Bábílónì.
Tàbí “ìkùukùu.”
Igi tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ fẹ̀, tó sì máa ń bó èèpo rẹ̀.
Ní Héb., “ìwọ.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “pẹ̀lú apá rẹ̀.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Ní Héb., “odò wọn.”
Ní Héb., “Ìwọ yóò sì kún inú àwọn ipadò.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “láìkọlà.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “Aláìkọlà.”
Tàbí “sàréè.”
Ní Héb., “gbogbo èèyàn rẹ̀.”
Ní Héb., “Sàréè rẹ̀.”
Tàbí “Aláìkọlà.”
Tàbí “tí kò kọlà.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ó lè jẹ́ bí wọ́n ṣe ń sin àwọn jagunjagun pẹ̀lú idà wọn láti fi yẹ́ àwọn ológun sí ló ń sọ.
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “àwọn olórí.”
Tàbí “láìkọlà.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Ní Héb., “tó sì mú un lọ.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọrùn olùṣọ́ náà ni màá ka ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “tí kò sì ṣe òdodo.”
Ní Héb., “rántí ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Tàbí “sọ̀rọ̀ ìfẹ́ orí ahọ́n.”
Tàbí “béèrè àwọn àgùntàn mi pa dà lọ́wọ́ wọn.”
Tàbí “bójú tó.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “oko tó lórúkọ.”
Tàbí “ìtàjẹ̀sílẹ̀.”
Ní Héb., “bí oúnjẹ.”
Ní Héb., “àṣẹ́kù; àwọn tó ṣẹ́ kù.”
Tàbí “kórìíra mi.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Ìyẹn, ọkàn tó ń jẹ́ kí Ọlọ́run darí òun.
Tàbí kó jẹ́, “Bí agbo àgùntàn tí wọ́n fi ń rúbọ ní Jerúsálẹ́mù.”
Tàbí “èémí; ẹ̀mí.”
Tàbí “ẹ̀mí.”
Tàbí “tí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.”
Tàbí “tí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ èèyàn rẹ.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
Tàbí “olórí.”
Tàbí “Ibùgbé; Ilé.”
Tàbí “lórí.”
Tàbí “olórí alákòóso.”
Tàbí “olórí alákòóso.”
Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.
Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.
Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.
Ní Héb., “ẹ̀ṣọ́.”
Tàbí “gbọ́ ìpè.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “tó ní ìgbèríko gbalasa.”
Tàbí “àwọn ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “olórí alákòóso.”
Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.
Tàbí kó jẹ́, ohun ìjà kan tó lẹ́nu ṣóńṣó.
Tàbí “Àfonífojì Ọ̀pọ̀ Rẹpẹtẹ Èèyàn Gọ́ọ̀gù.”
Ó túmọ̀ sí “Ọ̀pọ̀ Rẹpẹtẹ Èèyàn.”
Ní Héb., “ọwọ́.”
Ní Héb., “fi hàn pé orúkọ mímọ́ mi kò lẹ́gbẹ́.”
Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “fi ọkàn rẹ sí.”
Ní Héb., “ilé.” Ìtumọ̀ tó ní nìyẹn láti orí 40 sí 48 láwọn ibi tí “ilé” ti dúró fún apá kan nínú tẹ́ńpìlì tàbí tẹ́ńpìlì náà lápapọ̀.
Ní Héb., “ọ̀pá esùsú ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ìbú ọwọ́ kan.” Èyí túmọ̀ sí ìgbọ̀nwọ́ tó gùn. Wo Àfikún B14.
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orí ògiri yàrá ẹ̀ṣọ́ náà.
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “Wíńdò.”
Tàbí “Fèrèsé tó kéré lápá kan tó sì fẹ̀ lódìkejì.”
Tàbí “mo sì rí àwọn yàrá.”
Ní Héb., “Ó wá wọn fífẹ̀.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “Gọ̀bì.”
Tàbí “Gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “Gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí kó jẹ́, “12.”
Ní Héb., “tẹ́ńpìlì náà.” Ní orí 41 àti 42, ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ibi mímọ́ ìta (Ibi Mímọ́) tàbí gbogbo ibi mímọ́ (tẹ́ńpìlì náà, Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ).
Èyí ń tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ tó gùn. Wo Àfikún B14.
Ìyẹn, sínú ibi mímọ́ inú tàbí Ibi Mímọ́ Jù Lọ.
Ní Héb., “Ẹnu ọ̀nà náà fẹ̀ tó.”
Ó jọ pé àtẹ̀gùn ẹlẹ́lọ̀ọ́ ló ń sọ.
Ó jọ pé ọ̀nà tóóró kan tó yí tẹ́ńpìlì náà ká ni.
Tàbí “àwọn yàrá.”
Ìyẹn, ilé tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn ibi mímọ́.
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “wíńdò.”
Tàbí “àwọn fèrèsé tó kéré lápá kan tó sì fẹ̀ lódìkejì.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Ní Héb., “ni férémù.” Ó jọ pé ẹnu ọ̀nà Ibi Mímọ́ ló ń sọ.
Ó jọ pé Ibi Mímọ́ Jù Lọ ló ń sọ.
Ní Héb., “gígùn.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “Àwọn fèrèsé tó kéré lápá kan tó sì fẹ̀ lódìkejì.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Èyí túmọ̀ sí ìgbọ̀nwọ́ tó gùn. Wo Àfikún B14.
Tàbí “àwọn yàrá.”
“Gígùn rẹ̀ jẹ́ 100 ìgbọ̀nwọ́” gẹ́gẹ́ bí Bíbélì Septuagint Lédè Gíríìkì ṣe sọ ọ́. Bí wọ́n ṣe kọ ọ́ lédè Hébérù nìyí: “Ọ̀nà tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan.” Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “lára ibi tó fẹ̀ nínú.”
Ní Héb., “inú ilé.”
Wo Àfikún B14.
Tàbí kó jẹ́, “ó.”
Ní Héb., “ilé.”
Ní Héb., “mọ ìwọ̀n rẹ̀.”
Ó ń tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ tó gùn. Wo Àfikún B14.
Ìyẹn, nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 22.2 (ínǹṣì 8.75). Wo Àfikún B14.
Tàbí “àwọn ẹran tí ara wọn pé.”
Ìyẹn, ti àwọn èèyàn náà.
Tàbí “gọ̀bì.”
Ní Héb., “fọkàn sí i.”
Tàbí “dádọ̀dọ́.”
Tàbí “dádọ̀dọ́.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “àwọn yàrá mímọ́.”
Ó ń tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ tó gùn. Wo Àfikún B14.
Tàbí “Ilẹ̀ tó wà nínú gbogbo ààlà.”
Tàbí “20 yàrá.”
Wo Àfikún B14.
Wo Àfikún B14.
Wo Àfikún B14.
Wo Àfikún B14.
Wo Àfikún B14.
Tàbí “mínà.” Wo Àfikún B14.
Tàbí “wíìtì.”
Wo Àfikún B14.
Wo Àfikún B14.
Tàbí “gọ̀bì.”
Wo Àfikún B14.
Wo Àfikún B14.
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “àwọn yàrá mímọ́.”
Ó ń tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ tó gùn. Wo Àfikún B14.
Tàbí “Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti igun wọn dọ́gba.”
Ó ń tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ tó gùn.Wo Àfikún B14.
Tàbí “aṣálẹ̀ tó tẹ́jú.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “tí odò méjèèjì.”
Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.
Ní Héb., “kálukú bí arákùnrin rẹ̀.”
Ní Héb., “ó sì ti bọ́ sọ́wọ́ yín.”
Ìyẹn, Òkun Òkú.
Ní Héb., “apá gúúsù.”
Ìyẹn, Àfonífojì Íjíbítì.
Ní Héb., “apá gúúsù.”
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Ó ń tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ tó gùn. Wo Àfikún B14.
Ìyẹn, Àfonífojì Íjíbítì.
Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.