ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt 1 Àwọn Ọba 1:1-22:53
  • 1 Àwọn Ọba

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1 Àwọn Ọba
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Àwọn Ọba

ÀWỌN ỌBA KÌÍNÍ

1 Nígbà náà, Ọba Dáfídì ti darúgbó,+ ó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún* láyé, bí wọ́n tiẹ̀ ń fi aṣọ bò ó, òtútù ṣì máa ń mú un. 2 Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Jẹ́ kí a bá olúwa wa ọba wá ọmọbìnrin kan tó jẹ́ wúńdíá,* kó lè máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọba, kó sì máa tọ́jú rẹ̀. Ẹ̀gbẹ́ rẹ ni á máa sùn sí kí ara olúwa wa ọba lè móoru.” 3 Wọ́n wá ọmọbìnrin tó rẹwà kiri gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n rí Ábíṣágì+ ará Ṣúnémù,+ wọ́n sì mú un wá fún ọba. 4 Ọmọbìnrin náà lẹ́wà gan-an, ó di olùtọ́jú ọba, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ ọba kò bá a lò pọ̀.

5 Ní àkókò yìí, Ádóníjà+ ọmọkùnrin Hágítì ń gbé ara rẹ̀ ga, ó ń sọ pé: “Èmi ló máa di ọba!” Ó ní kí wọ́n ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún òun, ó kó àwọn agẹṣin jọ àti àádọ́ta (50) ọkùnrin tí á máa sáré níwájú rẹ̀.+ 6 Àmọ́ bàbá rẹ̀ kò bi í* pé: “Kí nìdí tí o fi ṣe báyìí?” Òun náà lẹ́wà gan-an, ìyá rẹ̀ sì bí i lẹ́yìn tí wọ́n bí Ábúsálómù. 7 Ó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Jóábù ọmọ Seruáyà àti àlùfáà Ábíátárì,+ wọ́n ran Ádóníjà lọ́wọ́, wọ́n sì tì í lẹ́yìn.+ 8 Àmọ́ àlùfáà Sádókù,+ Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà, wòlíì Nátánì,+ Ṣíméì,+ Réì àti àwọn akíkanjú jagunjagun Dáfídì+ kò ti Ádóníjà lẹ́yìn.

9 Níkẹyìn, Ádóníjà fi àgùntàn àti màlúù pẹ̀lú ẹran àbọ́sanra rúbọ+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkúta Sóhélétì, èyí tó wà nítòsí Ẹn-rógélì, ó pe gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àwọn ọmọ ọba àti gbogbo ọkùnrin Júdà tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ ọba. 10 Àmọ́ kò pe wòlíì Nátánì àti Bẹnáyà àti àwọn jagunjagun tó lákíkanjú, bẹ́ẹ̀ ni kò pe Sólómọ́nì àbúrò rẹ̀. 11 Nátánì+ wá sọ fún Bátí-ṣébà,+ ìyá Sólómọ́nì+ pé: “Ṣé o kò tíì gbọ́ pé Ádóníjà+ ọmọ Hágítì ti di ọba, olúwa wa Dáfídì kò sì mọ nǹkan kan nípa rẹ̀? 12 Ní báyìí, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n gbà ọ́ nímọ̀ràn, kí o lè dá ẹ̀mí ara rẹ àti ti* Sólómọ́nì ọmọ rẹ sí.+ 13 Wọlé lọ bá Ọba Dáfídì, kí o sọ fún un pé, ‘Olúwa mi ọba, ṣebí ìwọ lo búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé: “Sólómọ́nì ọmọ rẹ ló máa di ọba lẹ́yìn mi, òun ló sì máa jókòó sórí ìtẹ́ mi”?+ Kí ló dé tí Ádóníjà fi wá di ọba?’ 14 Nígbà tí o bá ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi náà á wọlé wá, màá sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ.”

15 Torí náà, Bátí-ṣébà wọlé lọ bá ọba nínú yàrá àdáni rẹ̀. Ọba ti darúgbó gan-an, Ábíṣágì+ ará Ṣúnémù sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba. 16 Ìgbà náà ni Bátí-ṣébà tẹrí ba, ó sì wólẹ̀ fún ọba, ọba wá sọ pé: “Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” 17 Ó dáhùn pé: “Olúwa mi, ìwọ lo fi Jèhófà Ọlọ́run rẹ búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé, ‘Sólómọ́nì ọmọ rẹ ló máa di ọba lẹ́yìn mi, òun ló sì máa jókòó sórí ìtẹ́ mi.’+ 18 Àmọ́ ní báyìí, Ádóníjà ti di ọba! Olúwa mi ọba kò sì mọ nǹkan kan nípa rẹ̀.+ 19 Ó fi akọ màlúù àti ẹran àbọ́sanra pẹ̀lú àgùntàn tó pọ̀ gan-an rúbọ, ó pe gbogbo ọmọ ọba àti àlùfáà Ábíátárì pẹ̀lú Jóábù olórí ọmọ ogun;+ àmọ́ kò pe Sólómọ́nì ìránṣẹ́ rẹ.+ 20 Ní báyìí, olúwa mi ọba, ojú rẹ ni gbogbo Ísírẹ́lì ń wò pé kí o sọ ẹni tó máa jókòó sórí ìtẹ́ olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ̀ fún wọn. 21 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ojú ọ̀dàlẹ̀ ni wọ́n máa fi wo èmi àti Sólómọ́nì ọmọ mi ní gbàrà tí olúwa mi ọba bá ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀.”

22 Nígbà tó ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wòlíì Nátánì wọlé.+ 23 Ní kíá, wọ́n sọ fún ọba pé: “Wòlíì Nátánì ti dé!” Ó wọlé síwájú ọba, ó tẹrí ba, ó sì wólẹ̀. 24 Ìgbà náà ni Nátánì sọ pé: “Olúwa mi ọba, ṣé o sọ pé, ‘Ádóníjà ló máa di ọba lẹ́yìn mi, òun ló sì máa jókòó sórí ìtẹ́ mi’?+ 25 Torí pé lónìí, ó ti lọ fi akọ màlúù àti ẹran àbọ́sanra pẹ̀lú àgùntàn tó pọ̀ gan-an rúbọ,+ ó pe gbogbo ọmọ ọba àti àwọn olórí ọmọ ogun pẹ̀lú àlùfáà Ábíátárì.+ Wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí wọ́n ń jẹ, tí wọ́n sì ń mu, wọ́n ń sọ pé, ‘Kí ẹ̀mí Ọba Ádóníjà gùn o!’ 26 Ṣùgbọ́n kò pe èmi ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò pe àlùfáà Sádókù àti Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà àti Sólómọ́nì ìránṣẹ́ rẹ. 27 Ṣé olúwa mi ọba ti fàṣẹ sí ọ̀rọ̀ yìí láìjẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ mọ ẹni tó yẹ kó jókòó sórí ìtẹ́ olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ̀ ni?”

28 Ọba Dáfídì wá fèsì pé: “Ẹ pe Bátí-ṣébà wá fún mi.” Ni ó bá wọlé, ó sì dúró síwájú ọba. 29 Ìgbà náà ni ọba búra pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tó yọ mí* nínú gbogbo wàhálà,+ 30 bí mo ṣe fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún ọ, tí mo sọ pé: ‘Sólómọ́nì ọmọ rẹ ló máa di ọba lẹ́yìn mi, òun ló sì máa jókòó sórí ìtẹ́ mi ní ipò mi!’ ohun tí màá ṣe nìyẹn lónìí yìí.” 31 Ìgbà náà ni Bátí-ṣébà tẹrí ba, ó dojú bolẹ̀ fún ọba, ó sì sọ pé: “Kí olúwa mi Ọba Dáfídì wà títí láé!”

32 Ní kíá, Ọba Dáfídì sọ pé: “Ẹ pe àlùfáà Sádókù àti wòlíì Nátánì àti Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà+ wá fún mi.” Torí náà, wọ́n wọlé síwájú ọba. 33 Ọba sọ fún wọn pé: “Ẹ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa yín dání, kí ẹ sì ní kí Sólómọ́nì ọmọ mi gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* tèmi fúnra mi,+ kí ẹ wá mú un lọ sí Gíhónì.+ 34 Àlùfáà Sádókù àti wòlíì Nátánì yóò fòróró yàn án+ níbẹ̀ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì; lẹ́yìn náà kí ẹ fun ìwo, kí ẹ sì sọ pé, ‘Kí ẹ̀mí Ọba Sólómọ́nì gùn o!’+ 35 Lẹ́yìn náà, kí ẹ tẹ̀ lé e pa dà, kó sì wọlé wá jókòó sórí ìtẹ́ mi; òun ló máa jọba ní ipò mi, màá sì yàn án láti jẹ́ aṣáájú Ísírẹ́lì àti Júdà.” 36 Ní kíá, Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà sọ fún ọba pé: “Àmín! Kí Jèhófà Ọlọ́run olúwa mi ọba fọwọ́ sí i. 37 Bí Jèhófà ṣe wà pẹ̀lú olúwa mi ọba, bẹ́ẹ̀ ni kí ó wà pẹ̀lú Sólómọ́nì,+ kí ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ olúwa mi Ọba Dáfídì.”+

38 Lẹ́yìn náà, àlùfáà Sádókù àti wòlíì Nátánì àti Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà pẹ̀lú àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ jáde lọ, wọ́n ní kí Sólómọ́nì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* Ọba Dáfídì,+ wọ́n sì mú un wá sí Gíhónì.+ 39 Ni àlùfáà Sádókù bá mú ìwo òróró+ láti inú àgọ́,+ ó sì fòróró yan Sólómọ́nì,+ wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í fun ìwo, gbogbo èèyàn náà sì ń kígbe pé: “Kí ẹ̀mí Ọba Sólómọ́nì gùn o!” 40 Lẹ́yìn náà, gbogbo èèyàn náà tẹ̀ lé e lọ, wọ́n ń fun fèrè, inú wọn sì dùn gan-an débi pé ariwo wọn fa ilẹ̀ ya.*+

41 Ádóníjà àti gbogbo àwọn tí ó pè gbọ́ nígbà tí wọ́n jẹun tán.+ Gbàrà tí Jóábù gbọ́ ìró ìwo, ó sọ pé: “Kí nìdí tí ariwo fi gba gbogbo ìlú kan?” 42 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Jónátánì+ ọmọ àlùfáà Ábíátárì dé. Ìgbà náà ni Ádóníjà sọ pé: “Wọlé wá, torí èèyàn dáadáa* ni ọ́, ó dájú pé ìròyìn ayọ̀ lo mú wá.” 43 Àmọ́ Jónátánì dá Ádóníjà lóhùn pé: “Rárá o! Ọba Dáfídì olúwa wa ti fi Sólómọ́nì jẹ ọba. 44 Ọba rán àlùfáà Sádókù àti wòlíì Nátánì àti Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà pẹ̀lú àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì tẹ̀ lé e, wọ́n sì ní kó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* ọba.+ 45 Lẹ́yìn náà, àlùfáà Sádókù àti wòlíì Nátánì fòróró yàn án ṣe ọba ní Gíhónì. Wọ́n wá kúrò níbẹ̀, inú wọn ń dùn, ariwo sì gba ìlú kan. Ariwo tí ẹ gbọ́ nìyẹn. 46 Yàtọ̀ síyẹn, Sólómọ́nì ti jókòó sórí ìtẹ́ ọba. 47 Ohun míì ni pé, àwọn ìránṣẹ́ ọba wọlé wá láti bá Ọba Dáfídì olúwa wa yọ̀, wọ́n sọ pé, ‘Kí Ọlọ́run rẹ mú kí orúkọ Sólómọ́nì gbayì ju orúkọ rẹ, kí ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ rẹ!’ Ni ọba bá tẹrí ba lórí ibùsùn. 48 Ọba sì sọ pé, ‘Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó fún mi ní ẹni tó máa jókòó sórí ìtẹ́ mi, tó sì jẹ́ kó ṣojú mi lónìí!’”

49 Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn tí Ádóníjà pè wá, kálukú wọn dìde, wọ́n sì bá tiwọn lọ. 50 Ẹ̀rù Sólómọ́nì ń ba Ádóníjà, torí náà, ó gbéra, ó sì lọ di àwọn ìwo pẹpẹ mú.+ 51 Wọ́n wá ròyìn fún Sólómọ́nì pé: “Wò ó, ẹ̀rù Ọba Sólómọ́nì ti ń ba Ádóníjà; ó sì ti lọ gbá àwọn ìwo pẹpẹ mú, ó sọ pé, ‘Kí Ọba Sólómọ́nì kọ́kọ́ búra fún mi pé òun ò ní fi idà pa ìránṣẹ́ rẹ̀.’” 52 Ni Sólómọ́nì bá sọ pé: “Tí kò bá kọjá àyè rẹ̀, kò sí ìkankan nínú irun orí rẹ̀ tó máa bọ́ sílẹ̀; àmọ́ tí a bá rí ohun tí kò dára lọ́wọ́ rẹ̀,+ ó gbọ́dọ̀ kú.” 53 Nítorí náà, Ọba Sólómọ́nì ní kí wọ́n lọ mú un wá láti ibi pẹpẹ. Lẹ́yìn náà, ó wọlé, ó sì tẹrí ba fún Ọba Sólómọ́nì, Sólómọ́nì wá sọ fún un pé: “Máa lọ sí ilé rẹ.”

2 Nígbà tí ikú Dáfídì ń sún mọ́lé, ó sọ àwọn nǹkan tí Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ máa ṣe fún un, ó ní: 2 “Mi ò ní pẹ́ kú.* Torí náà, jẹ́ alágbára,+ kí o sì ṣe bí ọkùnrin.+ 3 Máa ṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní kí o ṣe, kí o máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ àti àwọn àṣẹ rẹ̀, àwọn ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránnilétí rẹ̀, bí wọ́n ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè;+ ìgbà náà ni wàá ṣàṣeyọrí* nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àti níbikíbi tí o bá yíjú sí. 4 Jèhófà á sì mú ìlérí tó ṣe nípa mi ṣẹ, pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá fiyè sí ọ̀nà wọn, láti fi òtítọ́ rìn níwájú mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo ara* wọn,+ kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ* tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’+

5 “Ìwọ náà mọ ohun tí Jóábù ọmọ Seruáyà ṣe sí mi dáadáa, ohun tó ṣe sí àwọn olórí ọmọ ogun Ísírẹ́lì méjì, ìyẹn Ábínérì+ ọmọ Nérì àti Ámásà+ ọmọ Jétà. Ó pa wọ́n nígbà tí kì í ṣe pé ogun ń jà, ó mú kí ẹ̀jẹ̀+ ogun ta sára àmùrè tó sán mọ́ ìbàdí rẹ̀ àti sára bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀. 6 Ṣe ohun tó yẹ gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, má sì jẹ́ kó fọwọ́ rọrí kú.*+

7 “Àmọ́ kí o fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn ọmọ Básíláì+ ọmọ Gílíádì, kí wọ́n sì wà lára àwọn tí á máa jẹun lórí tábìlì rẹ, nítorí bí wọ́n ṣe dúró tì mí+ nìyẹn nígbà tí mo sá lọ nítorí Ábúsálómù+ ẹ̀gbọ́n rẹ.

8 “Ṣíméì ọmọ Gérà ọmọ Bẹ́ńjámínì láti Báhúrímù náà wà nítòsí rẹ. Òun ló ń ṣẹ́ èpè burúkú+ lé mi lórí lọ́jọ́ tí mò ń lọ sí Máhánáímù;+ àmọ́ nígbà tó wá pàdé mi ní Jọ́dánì, mo fi Jèhófà búra fún un pé: ‘Mi ò ní fi idà pa ọ́.’+ 9 Má ṣàìfi ìyà jẹ ẹ́,+ nítorí ọlọ́gbọ́n ni ọ́, o sì mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe sí i; má ṣe jẹ́ kí ó fọwọ́ rọrí kú.”*+

10 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì.+ 11 Gbogbo ọdún* tí Dáfídì fi jọba lórí Ísírẹ́lì jẹ́ ogójì (40) ọdún. Ọdún méje ló fi jọba ní Hébúrónì,+ ó sì fi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33)+ jọba ní Jerúsálẹ́mù.

12 Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìjọba rẹ̀ fìdí múlẹ̀ gbọn-in.+

13 Nígbà tó yá, Ádóníjà ọmọ Hágítì wá sọ́dọ̀ Bátí-ṣébà, ìyá Sólómọ́nì. Bátí-ṣébà béèrè pé: “Ṣé àlàáfíà lo bá wá o?” Ó fèsì pé: “Àlàáfíà ni.” 14 Ó wá sọ pé: “Ohun kan wà tí mo fẹ́ sọ fún ọ.” Torí náà, ó sọ pé: “Sọ ọ́.” 15 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “O mọ̀ dáadáa pé èmi ni ọba tọ́ sí, gbogbo Ísírẹ́lì sì ń retí* pé màá di ọba;+ ṣùgbọ́n ó bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́, ó sì di ti àbúrò mi, nítorí pé Jèhófà lọ́wọ́ sí i ló ṣe di tirẹ̀.+ 16 Àmọ́ ní báyìí, ohun kan péré ni mo fẹ́ tọrọ lọ́wọ́ rẹ. Má ṣe da ọ̀rọ̀ mi nù.” Torí náà, ó sọ fún un pé: “Sọ ọ́.” 17 Ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún Sólómọ́nì ọba pé kó fún mi ní Ábíṣágì+ ará Ṣúnémù láti fi ṣe aya. Mo mọ̀ pé kò ní da ọ̀rọ̀ rẹ nù.” 18 Bátí-ṣébà fèsì pé: “Ó dáa! Màá bá ọ sọ fún ọba.”

19 Nítorí náà, Bátí-ṣébà wọlé lọ sọ́dọ̀ Ọba Sólómọ́nì kí ó lè bá a sọ̀rọ̀ nítorí Ádóníjà. Ní kíá, ọba dìde láti pàdé rẹ̀, ọba sì tẹrí ba fún un. Lẹ́yìn náà, ó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ní kí wọ́n gbé ìtẹ́ kan wá fún ìyá ọba, kí ó lè jókòó sí apá ọ̀tún rẹ̀. 20 Ìgbà náà ni Bátí-ṣébà sọ pé: “Ohun kékeré kan wà tí mo fẹ́ béèrè lọ́wọ́ rẹ. Má ṣe da ọ̀rọ̀ mi nù.” Torí náà, ọba sọ fún un pé: “Béèrè, ìyá mi; mi ò ní da ọ̀rọ̀ rẹ nù.” 21 Ó sọ pé: “Jẹ́ kí a fún Ádóníjà ẹ̀gbọ́n rẹ ní Ábíṣágì ará Ṣúnémù láti fi ṣe aya.” 22 Ni Ọba Sólómọ́nì bá dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé: “Kí ló dé tí o fi ní kí n fún Ádóníjà ní Ábíṣágì ará Ṣúnémù? Ò bá kúkú ní kí n fún un ní ìjọba pẹ̀lú+ nítorí pé ẹ̀gbọ́n mi ni,+ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ni àlùfáà Ábíátárì àti Jóábù+ ọmọ Seruáyà+ wà.”

23 Ni Ọba Sólómọ́nì bá fi Jèhófà búra pé: “Kí Ọlọ́run fìyà jẹ mí gan-an, tí kò bá jẹ́ pé ohun tó máa gbẹ̀mí* Ádóníjà ló ń béèrè yìí. 24 Ní báyìí, bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tí ó fìdí mi múlẹ̀ gbọn-in,+ tí ó mú mi jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì bàbá mi, tí ó sì kọ́ ilé fún mi*+ bí ó ti ṣèlérí, òní ni a ó pa Ádóníjà.”+ 25 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ọba Sólómọ́nì rán Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà, ó jáde lọ, ó ṣá Ádóníjà balẹ̀,* ó sì kú.

26 Ọba sọ fún àlùfáà Ábíátárì+ pé: “Lọ sí ilẹ̀ rẹ ní Ánátótì!+ Ikú tọ́ sí ọ, àmọ́ mi ò ní pa ọ́ lónìí yìí, torí pé o gbé Àpótí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ níwájú Dáfídì bàbá mi+ àti nítorí pé o jẹ nínú gbogbo ìyà tó jẹ bàbá mi.”+ 27 Nítorí náà, Sólómọ́nì lé Ábíátárì kúrò lẹ́nu ṣíṣe àlùfáà fún Jèhófà, láti mú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ sí ilé Élì+ ní Ṣílò+ ṣẹ.

28 Nígbà tí Jóábù gbọ́ ìròyìn náà, ó sá lọ sínú àgọ́ Jèhófà,+ ó sì di àwọn ìwo pẹpẹ mú, torí pé ẹ̀yìn Ádóníjà+ ni Jóábù wà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ti Ábúsálómù+ lẹ́yìn. 29 Ìgbà náà ni wọ́n wá sọ fún Ọba Sólómọ́nì pé: “Jóábù ti sá lọ sínú àgọ́ Jèhófà, ó sì wà níbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ.” Torí náà, Sólómọ́nì rán Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà pé: “Lọ pa á!” 30 Lẹ́yìn náà, Bẹnáyà lọ sínú àgọ́ Jèhófà, ó sọ fún Jóábù pé: “Ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Jáde wá!’” Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Rárá! Ibí ni màá kú sí.” Bẹnáyà pa dà wá sọ fún ọba pé: “Ohun tí Jóábù sọ nìyí, èsì tó sì fún mi nìyí.” 31 Ni ọba bá sọ fún un pé: “Ohun tí ó sọ ni kí o ṣe; ṣá a balẹ̀, kí o sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ tí Jóábù ta sílẹ̀ láìyẹ+ kúrò lórí mi àti kúrò lórí ilé bàbá mi. 32 Jèhófà yóò mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sórí rẹ̀, nítorí ó fi idà ṣá àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n lóòótọ́ jù ú lọ balẹ̀, tí wọ́n sì dára jù ú, ó pa wọ́n láìjẹ́ kí Dáfídì bàbá mi mọ̀. Àwọn ọkùnrin náà ni: Ábínérì+ ọmọ Nérì, olórí ọmọ ogun Ísírẹ́lì+ àti Ámásà+ ọmọ Jétà, olórí ọmọ ogun Júdà.+ 33 Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wá sórí Jóábù àti sórí àwọn ọmọ* rẹ̀ títí láé;+ àmọ́ kí àlàáfíà Jèhófà wà lórí Dáfídì àti àwọn ọmọ* rẹ̀, kí ó wà lórí ilé rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ títí láé.” 34 Ìgbà náà ni Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà lọ ṣá Jóábù balẹ̀, ó pa á, wọ́n sì sin ín sí ilé rẹ̀ ní aginjù. 35 Lẹ́yìn náà, ọba yan Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà ṣe olórí ọmọ ogun ní ipò rẹ̀, ọba tún yan àlùfáà Sádókù+ sí ipò Ábíátárì.

36 Nígbà náà, ọba ránṣẹ́ pe Ṣíméì,+ ó sì sọ fún un pé: “Kọ́ ilé kan fún ara rẹ ní Jerúsálẹ́mù, kí o sì máa gbé ibẹ̀; má ṣe kúrò níbẹ̀ lọ sí ibikíbi. 37 Ọjọ́ tí o bá jáde síta, tí o sì sọdá Àfonífojì Kídírónì,+ mọ̀ dájú pé wàá kú. Ẹ̀jẹ̀ rẹ á sì wà lórí ìwọ fúnra rẹ.” 38 Ṣíméì dá ọba lóhùn pé: “Ohun tí o sọ dára. Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe ohun tí olúwa mi ọba sọ.” Torí náà, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni Ṣíméì fi gbé ní Jerúsálẹ́mù.

39 Àmọ́ nígbà tí ọdún mẹ́ta kọjá, méjì lára àwọn ẹrú Ṣíméì sá lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì+ ọmọ Máákà ọba Gátì. Nígbà tí wọ́n sọ fún Ṣíméì pé: “Wò ó! Àwọn ẹrú rẹ wà ní Gátì,” 40 lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ṣíméì de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀,* ó sì lọ rí Ákíṣì ní Gátì láti wá àwọn ẹrú rẹ̀. Nígbà tí Ṣíméì kó àwọn ẹrú rẹ̀ dé láti Gátì, 41 wọ́n sọ fún Sólómọ́nì pé: “Ṣíméì jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Gátì, ó sì ti pa dà.” 42 Ni ọba bá ránṣẹ́ pe Ṣíméì, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé mi ò fi Jèhófà búra fún ọ, tí mo sì kìlọ̀ fún ọ pé: ‘Ọjọ́ tí o bá jáde kúrò níbí lọ sí ibikíbi, mọ̀ dájú pé wàá kú’? Ṣebí o sọ fún mi pé, ‘Ohun tí o sọ dára; màá ṣègbọràn’?+ 43 Kí wá nìdí tí o kò fi pa ìbúra Jèhófà mọ́ àti àṣẹ tí mo pa fún ọ?” 44 Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Ṣíméì pé: “Nínú ọkàn rẹ, o mọ gbogbo jàǹbá tí o ṣe fún Dáfídì bàbá mi,+ Jèhófà yóò sì dá jàǹbá náà pa dà sórí rẹ.+ 45 Àmọ́ Ọba Sólómọ́nì yóò gba ìbùkún,+ ìtẹ́ Dáfídì yóò sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in níwájú Jèhófà títí láé.” 46 Ni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà, Bẹnáyà jáde lọ, ó ṣá a balẹ̀, ó sì kú.+

Bí ìjọba náà ṣe fìdí múlẹ̀ gbọn-in lọ́wọ́ Sólómọ́nì nìyẹn.+

3 Sólómọ́nì bá Fáráò ọba Íjíbítì dána. Ó fẹ́* ọmọbìnrin Fáráò,+ ó sì mú un wá sí Ìlú Dáfídì+ títí ó fi kọ́ ilé rẹ̀ parí+ àti ilé Jèhófà+ pẹ̀lú ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká.+ 2 Àmọ́ àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ ní àwọn ibi gíga,+ nítorí títí di àkókò yẹn, wọn ò tíì kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà.+ 3 Ìfẹ́ Jèhófà wà lọ́kàn Sólómọ́nì bó ṣe ń rìn nínú òfin Dáfídì bàbá rẹ̀, kìkì pé ó ń rúbọ ní àwọn ibi gíga, ó sì ń mú àwọn ọrẹ rú èéfín níbẹ̀.+

4 Ọba lọ sí Gíbíónì láti rúbọ níbẹ̀, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga+ tí àwọn èèyàn mọ̀* jù lọ. Ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ẹbọ sísun ni Sólómọ́nì rú lórí pẹpẹ náà.+ 5 Ní Gíbíónì, Jèhófà fara han Sólómọ́nì lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì sọ pé: “Béèrè ohun tí wàá fẹ́ kí n fún ọ.”+ 6 Ni Sólómọ́nì bá sọ pé: “O ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dáfídì bàbá mi, lọ́nà tó ga, bó ṣe rìn níwájú rẹ ní òtítọ́ àti ní òdodo pẹ̀lú ọkàn tó dúró ṣinṣin. Títí di òní yìí, ò ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ kan náà hàn sí i lọ́nà tó ga tí o fi fún un ní ọmọkùnrin kan láti jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀.+ 7 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi, o ti fi ìránṣẹ́ rẹ jọba ní ipò Dáfídì bàbá mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́* ni mí, tí mi ò sì ní ìrírí.*+ 8 Ìránṣẹ́ rẹ wà lára àwọn èèyàn rẹ tí o yàn,+ àwọn èèyàn tó pọ̀ gan-an débi pé wọn ò níye, wọn ò sì ṣeé kà. 9 Torí náà, fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọkàn tó ń gbọ́ràn láti máa fi ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ,+ láti fi mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú,+ torí ta ló lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ tó pọ̀ gan-an* yìí?”

10 Ohun tí Sólómọ́nì béèrè yìí dára lójú Jèhófà.+ 11 Ọlọ́run wá sọ fún un pé: “Nítorí o kò béèrè ẹ̀mí gígùn* fún ara rẹ tàbí ọrọ̀ tàbí ikú* àwọn ọ̀tá rẹ, àmọ́ o béèrè òye láti máa gbọ́ àwọn ẹjọ́,+ 12 màá ṣe ohun tí o béèrè.+ Màá fún ọ ní ọkàn ọgbọ́n àti òye,+ tó fi jẹ́ pé bí kò ṣe sí ẹni tó dà bí rẹ ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ẹni tó máa dà bí rẹ mọ́.+ 13 Yàtọ̀ síyẹn, màá fún ọ ní ohun tí o kò béèrè,+ àti ọrọ̀ àti ògo,+ tó fi jẹ́ pé kò ní sí ọba míì tó máa dà bí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé* rẹ.+ 14 Tí o bá sì rìn ní àwọn ọ̀nà mi, tí ò ń pa àwọn ìlànà àti àṣẹ mi mọ́, bí Dáfídì bàbá rẹ ṣe rìn,+ màá tún fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.”*+

15 Nígbà tí Sólómọ́nì jí, ó rí i pé àlá ni. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó dúró níwájú àpótí májẹ̀mú Jèhófà, ó rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ ó sì se àsè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

16 Ní àkókò yẹn, àwọn aṣẹ́wó méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀. 17 Obìnrin àkọ́kọ́ sọ pé: “Jọ̀ọ́, olúwa mi, inú ilé kan náà ni èmi àti obìnrin yìí ń gbé, ó sì wà nílé nígbà tí mo bímọ. 18 Ọjọ́ kẹta lẹ́yìn tí mo bímọ, obìnrin yìí náà bímọ. Àwa méjèèjì nìkan la wà nílé; kò sí ẹlòmíì tó wà pẹ̀lú wa. 19 Ọmọ obìnrin yìí kú ní òru, torí pé ó sùn lé e. 20 Torí náà, ó dìde láàárín òru, ó sì gbé ọmọ mi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nígbà tí ẹrúbìnrin rẹ ń sùn lọ́wọ́, ó tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì tẹ́ ọmọ rẹ̀ tó ti kú sí àyà mi. 21 Nígbà tí mo dìde láàárọ̀ láti tọ́jú ọmọ mi, mo rí i pé ó ti kú. Torí náà, mo yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní ní àárọ̀ yẹn, mo sì rí i pé kì í ṣe ọmọ tí mo bí.” 22 Ṣùgbọ́n obìnrin kejì sọ pé: “Rárá, ọmọ tèmi ló wà láàyè, ọmọ tìrẹ ló kú!” Síbẹ̀ obìnrin àkọ́kọ́ ń sọ pé: “Rárá o, ọmọ tèmi ló wà láàyè, ọmọ tìrẹ ló kú.” Bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn jiyàn nìyẹn níwájú ọba.

23 Níkẹyìn, ọba sọ pé: “Ẹni tibí ń sọ pé, ‘Ọmọ tó wà láàyè ni ọmọ mi, èyí tó ti kú ni ọmọ tìrẹ!’ ẹni tọ̀hún sì ń sọ pé, ‘Rárá, ọmọ tìrẹ ló kú, ọmọ tèmi ló wà láàyè!’” 24 Ọba wá sọ pé: “Ẹ bá mi mú idà kan wá.” Torí náà, wọ́n mú idà kan wá fún ọba. 25 Ni ọba bá sọ pé: “Ẹ la ààyè ọmọ náà sí méjì, kí ẹ fún obìnrin àkọ́kọ́ ní ìdajì, kí ẹ sì fún èkejì ní ìdajì.” 26 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin tó ni ààyè ọmọ náà bẹ ọba torí pé ara ọmọ ta á. Ó sọ pé: “Jọ̀wọ́, olúwa mi! Ẹ fún un ní ààyè ọmọ náà! Ẹ má pa á!” Àmọ́ obìnrin kejì ń sọ pé: “Kò ní jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ ni kò ní jẹ́ tìrẹ! Ẹ là á sí méjì!” 27 Ni ọba bá dáhùn pé: “Ẹ fún obìnrin àkọ́kọ́ ní ààyè ọmọ náà! Ẹ má pa á, torí òun ni ìyá rẹ̀.”

28 Nítorí náà, gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, ohun tí ọba ṣe yìí sì jọ wọ́n lójú gidigidi,*+ torí wọ́n rí i pé ó ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.+

4 Ọba Sólómọ́nì ṣàkóso lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+ 2 Àwọn ìjòyè* rẹ̀ nìyí: Asaráyà ọmọ Sádókù+ ni àlùfáà; 3 Élíhóréfì àti Áhíjà, àwọn ọmọ Ṣíṣà ni akọ̀wé;+ Jèhóṣáfátì+ ọmọ Áhílúdù ni akọ̀wé ìrántí; 4 Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà ló ń bójú tó àwọn ọmọ ogun; Sádókù àti Ábíátárì+ sì jẹ́ àlùfáà; 5 Asaráyà ọmọ Nátánì+ ni olórí àwọn alábòójútó; Sábúdù ọmọ Nátánì jẹ́ àlùfáà àti ọ̀rẹ́ ọba;+ 6 Áhíṣà ló ń bójú tó agbo ilé; Ádónírámù+ ọmọ Ábídà ni olórí àwọn tí ọba ní kí ó máa ṣiṣẹ́ fún òun.+

7 Sólómọ́nì ní àwọn alábòójútó méjìlá (12) tó ń bójú tó gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni láti pèsè oúnjẹ ní oṣù kan lọ́dún.+ 8 Àwọn alábòójútó náà ni: Ọmọ Húrì tó ń bójú tó agbègbè olókè Éfúrémù; 9 ọmọ Dékérì tó ń bójú tó Mákásì, Ṣáálíbímù,+ Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti Eloni-bẹti-hánánì; 10 ọmọ Hésédì tó ń bójú tó Árúbótì (tirẹ̀ ni Sókọ̀ àti gbogbo ilẹ̀ Héfà); 11 ọmọ Ábínádábù tó ń bójú tó gbogbo gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Dórì (ó fi Táfátì, ọmọ Sólómọ́nì ṣe aya); 12 Béánà ọmọ Áhílúdù tó ń bójú tó Táánákì, Mẹ́gídò+ àti gbogbo Bẹti-ṣéánì+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Sárétánì nísàlẹ̀ Jésírẹ́lì, láti Bẹti-ṣéánì sí Ebẹli-méhólà títí dé agbègbè Jókíméámù;+ 13 ọmọ Gébérì tó ń bójú tó Ramoti-gílíádì+ (tirẹ̀ ni àwọn abúlé àgọ́ Jáírì+ ọmọ Mánásè, tó wà ní Gílíádì;+ òun ló tún ni agbègbè Ágóbù,+ tó wà ní Báṣánì:+ ọgọ́ta [60] ìlú tó tóbi, tó sì ní ògiri àti ọ̀pá ìdábùú bàbà); 14 Áhínádábù ọmọ Ídò tó ń bójú tó Máhánáímù;+ 15 Áhímáásì tó ń bójú tó Náfútálì (ó fi Básémátì, tó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Sólómọ́nì, ṣe aya); 16 Béánà ọmọ Húṣáì, tó ń bójú tó Áṣérì àti Béálótì; 17 Jèhóṣáfátì ọmọ Párúà tó ń bójú tó Ísákà; 18 Ṣíméì+ ọmọ Ílà tó ń bójú tó Bẹ́ńjámínì;+ 19 Gébérì ọmọ Úráì tó ń bójú tó ilẹ̀ Gílíádì,+ ilẹ̀ Síhónì+ ọba àwọn Ámórì àti ti Ógù+ ọba Báṣánì. Alábòójútó kan tún wà tó ń bójú tó gbogbo àwọn alábòójútó yòókù ní ilẹ̀ náà.

20 Júdà àti Ísírẹ́lì pọ̀ bí iyanrìn etí òkun;+ wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń yọ̀.+

21 Sólómọ́nì ṣàkóso gbogbo àwọn ìjọba láti Odò*+ dé ilẹ̀ àwọn Filísínì àti títí dé ààlà Íjíbítì. Wọ́n ń mú ìṣákọ́lẹ̀* wá, wọ́n sì ń sin Sólómọ́nì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.+

22 Oúnjẹ Sólómọ́nì ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n (30) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta (60) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ìyẹ̀fun, 23 màlúù àbọ́sanra mẹ́wàá, ogún (20) màlúù láti ibi ìjẹko àti ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, yàtọ̀ sí àwọn akọ àgbọ̀nrín mélòó kan, àwọn egbin, àwọn èsúwó àti àwọn ẹ̀lúlùú tí ó sanra. 24 Ó ń bójú tó gbogbo ohun tó wà lápá Odò+ níbí,* láti Tífísà dé Gásà,+ títí kan gbogbo àwọn ọba tó wà lápá Odò níbí; ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo agbègbè tó yí i ká.+ 25 Júdà àti Ísírẹ́lì ń gbé lábẹ́ ààbò ní gbogbo ọjọ́ ayé Sólómọ́nì, kálukú lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà.

26 Sólómọ́nì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000)* ilé ẹṣin fún àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin.*+

27 Àwọn alábòójútó yìí ń pèsè oúnjẹ fún Ọba Sólómọ́nì àti gbogbo àwọn tó ń jẹun ní tábìlì Ọba Sólómọ́nì. Kálukú ní oṣù tirẹ̀ tó ń pèsè oúnjẹ, á sì rí i dájú pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò ló wà.+ 28 Wọ́n á tún mú ọkà bálì àti pòròpórò wá níbikíbi tí a bá ti nílò rẹ̀ fún àwọn ẹṣin títí kan àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ẹṣin, bí iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún kálukú wọn bá ṣe gbà.

29 Ọlọ́run fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye tó pọ̀ gan-an àti ìjìnlẹ̀ òye tó pọ̀* bí iyanrìn etí òkun.+ 30 Ọgbọ́n Sólómọ́nì pọ̀ ju ọgbọ́n gbogbo àwọn ará Ìlà Oòrùn àti gbogbo ọgbọ́n Íjíbítì.+ 31 Ó gbọ́n ju èèyàn èyíkéyìí lọ, ó gbọ́n ju Étánì+ tó jẹ́ Ẹ́síráhì àti Hémánì,+ Kálíkólì+ àti Dáádà, àwọn ọmọ Máhólì; òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí i ká.+ 32 Ó kọ* ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) òwe,+ àwọn orin rẹ̀+ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé márùn-ún (1,005). 33 Ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn igi, látorí kédárì tó wà ní Lẹ́bánónì dórí hísópù+ tó ń hù lára ògiri; ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko,+ àwọn ẹyẹ,*+ àwọn ohun tó ń rákò*+ àti àwọn ẹja. 34 Àwọn èèyàn ń wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè kí wọ́n lè gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì, títí kan àwọn ọba láti ibi gbogbo láyé tí wọ́n ti gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.+

5 Nígbà tí Hírámù ọba Tírè+ gbọ́ pé a ti fòróró yan Sólómọ́nì láti jọba ní ipò bàbá rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí Sólómọ́nì, nítorí tipẹ́tipẹ́ ni Hírámù ti jẹ́ ọ̀rẹ́* Dáfídì.+ 2 Ni Sólómọ́nì bá ránṣẹ́ sí Hírámù+ pé: 3 “O mọ̀ dáadáa pé Dáfídì bàbá mi kò lè kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ nítorí ogun tí wọ́n fi yí i ká, títí Jèhófà fi fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.+ 4 Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi yí ká.+ Kò sí alátakò kankan, láburú kankan ò sì ṣẹlẹ̀.+ 5 Torí náà, mo fẹ́ kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi, bí Jèhófà ti ṣèlérí fún Dáfídì bàbá mi pé: ‘Ọmọ rẹ tí màá fi sórí ìtẹ́ rẹ láti rọ́pò rẹ ni ó máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.’+ 6 Ní báyìí, sọ fún àwọn èèyàn rẹ pé kí wọ́n gé igi kédárì ti Lẹ́bánónì+ fún mi. Àwọn ìránṣẹ́ mi á bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣiṣẹ́, màá san owó iṣẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, iye tí o bá sì sọ ni màá san, nítorí o mọ̀ pé kò sí ìkankan lára wa tó mọ bí a ṣe ń gé igi bí àwọn ọmọ Sídónì.”+

7 Nígbà tí Hírámù gbọ́ ohun tí Sólómọ́nì sọ, inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà lónìí, nítorí ó ti fún Dáfídì ní ọlọ́gbọ́n ọmọ tó máa darí ọ̀pọ̀ èèyàn* yìí!”+ 8 Torí náà, Hírámù ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì pé: “Mo ti gbọ́ iṣẹ́ tí o rán sí mi. Màá ṣe gbogbo ohun tí o fẹ́, màá fún ọ ní gẹdú igi kédárì àti igi júnípà.+ 9 Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kó wọn wá láti Lẹ́bánónì sí òkun, màá dì wọ́n ní àdìpọ̀ igi gẹdú kí ó lè gba orí òkun lọ sí ibi tí o bá ní kí n kó wọn sí. Màá ní kí wọ́n la àwọn igi náà níbẹ̀, kí o lè kó wọn lọ. Oúnjẹ tí mo bá béèrè fún agbo ilé+ mi ni wàá fi san án pa dà fún mi.”

10 Nítorí náà, Hírámù fún Sólómọ́nì ní gbogbo gẹdú igi kédárì àti igi júnípà tó fẹ́. 11 Sólómọ́nì fún Hírámù ní ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* àlìkámà* kó lè jẹ́ oúnjẹ fún agbo ilé rẹ̀ àti ogún (20) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ògidì òróró ólífì.* Ohun tí Sólómọ́nì máa ń fún Hírámù nìyẹn lọ́dọọdún.+ 12 Jèhófà fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n, bí ó ti ṣèlérí fún un.+ Àlàáfíà wà láàárín Hírámù àti Sólómọ́nì, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn.*

13 Ọba Sólómọ́nì ní kí àwọn ọkùnrin kan láti gbogbo Ísírẹ́lì máa ṣiṣẹ́ fún òun;+ wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) ọkùnrin. 14 Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lára wọn ló máa ń rán lọ sí Lẹ́bánónì lóṣooṣù láti gba iṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn. Wọ́n á lo oṣù kan ní Lẹ́bánónì, wọ́n á sì lo oṣù méjì ní ilé wọn; Ádónírámù+ sì ni olórí àwọn tí ọba ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun. 15 Sólómọ́nì ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) lébìrà* àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) àwọn tó ń gé òkúta+ ní àwọn òkè+ 16 àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (3,300) ìjòyè+ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ àbójútó láti máa darí àwọn òṣìṣẹ́. 17 Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n fọ́ àwọn òkúta ńláńlá, àwọn òkúta iyebíye,+ kí wọ́n lè fi òkúta tí wọ́n bá gbẹ́+ ṣe ìpìlẹ̀ ilé+ náà. 18 Torí náà, àwọn kọ́lékọ́lé Sólómọ́nì àti ti Hírámù pẹ̀lú àwọn ará Gébálì+ gé àwọn òkúta náà, wọ́n sì ṣètò àwọn gẹdú àti àwọn òkúta tí wọ́n máa fi kọ́ ilé náà.

6 Ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgọ́rin (480) ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ní ọdún kẹrin lẹ́yìn tí Sólómọ́nì di ọba lórí Ísírẹ́lì, ní oṣù Sífì*+ (ìyẹn, oṣù kejì), ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé Jèhófà.*+ 2 Ilé tí Ọba Sólómọ́nì kọ́ fún Jèhófà jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́* ní gígùn, ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́ ní gíga.+ 3 Ibi àbáwọlé*+ tó wà níwájú tẹ́ńpìlì* náà jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn,* ó sì bá fífẹ̀ ilé náà mu.* Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ló fi yọ síta lára iwájú ilé náà.

4 Ó ṣe àwọn fèrèsé* tí férémù wọn fẹ̀ lápá kan tó sì kéré lódìkejì*+ sí ilé náà. 5 Ó tún mọ ògiri kan ti ògiri ilé náà; ògiri náà yí àwọn ògiri ilé náà ká, ìyẹn ti tẹ́ńpìlì* àti ti yàrá inú lọ́hùn-ún,+ ó sì ṣe àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ sínú rẹ̀ yí ká.+ 6 Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ tó wà ní ìsàlẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní fífẹ̀, ti àárín jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní fífẹ̀, ti ìkẹta tó sì wà lókè jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méje ní fífẹ̀, nítorí ó gé àwọn ibì kan sínú lára* ilé náà yí ká, kí ohunkóhun má bàa wọnú ògiri ilé náà.+

7 Àwọn òkúta tí wọ́n ti gbẹ́ sílẹ̀+ ni wọ́n fi kọ́ ilé náà, tí a kò fi gbọ́ ìró òòlù, àáké tàbí ohun èlò irin kankan nínú ilé náà nígbà tí wọ́n ń kọ́ ọ lọ́wọ́. 8 Ẹnu ọ̀nà tó wọ yàrá ẹ̀gbẹ́ tó wà ní ìsàlẹ̀ wà lápá gúúsù* ilé náà,+ àtẹ̀gùn tó yí po ni wọ́n ń gbà gòkè lọ sí yàrá àárín àti láti yàrá àárín dé yàrá kẹta tó wà lókè. 9 Ó kọ́ ilé náà títí ó fi parí rẹ̀,+ ó fi igi kédárì ṣe igi àjà àti pákó+ tó fi bo ilé náà. 10 Ó kọ́ àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ yí ilé náà ká,+ gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, àwọn gẹdú igi kédárì ni ó sì fi mú wọn mọ́ ara ilé náà.

11 Ní àkókò yìí, Jèhófà bá Sólómọ́nì sọ̀rọ̀, ó ní: 12 “Ní ti ilé tí ò ń kọ́ yìí, tí o bá rìn nínú àwọn òfin mi, tí o pa àwọn ìdájọ́ mi mọ́, tí o pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, tí o sì ń rìn nínú wọn,+ èmi náà á mú ìlérí tí mo ṣe fún Dáfídì bàbá rẹ ṣẹ,+ 13 èmi yóò máa gbé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ mi ò sì ní fi àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì+ sílẹ̀.”

14 Sólómọ́nì ń bá iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà lọ kí ó lè parí rẹ̀. 15 Ó fi àwọn pátákó kédárì bo* àwọn ògiri inú ilé náà. Ó fi àwọn ẹ̀là gẹdú bo ògiri inú, láti ìsàlẹ̀ ilé náà títí dé àwọn igi ìrólé tó wà ní àjà, ó sì fi àwọn pátákó júnípà+ bo ilẹ̀ ilé náà. 16 Ó fi pátákó kédárì ṣe apá kan tí ó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ìsàlẹ̀ ilé náà títí dé àwọn igi ìrólé, ó sì kọ́ Ibi Mímọ́ Jù Lọ+ sínú rẹ̀,* èyí ni yàrá inú lọ́hùn-ún.+ 17 Ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́ sì ni apá tó kù níwájú ilé náà, èyí ni tẹ́ńpìlì.*+ 18 Àwọn akèrègbè+ àti ìtànná òdòdó+ ni wọ́n gbẹ́ sára igi kédárì tí ó wà nínú ilé náà. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ igi kédárì; kò sí òkúta kankan tí a rí.

19 Ó ṣètò yàrá inú lọ́hùn-ún+ ilé náà kí ó lè gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà síbẹ̀.+ 20 Gígùn yàrá inú lọ́hùn-ún náà jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́;+ ó sì fi ògidì wúrà bò ó; ó fi igi kédárì bo pẹpẹ náà.+ 21 Sólómọ́nì fi ògidì wúrà+ bo inú ilé náà, ó na ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi wúrà ṣe sí iwájú yàrá inú lọ́hùn-ún,+ èyí tí wọ́n fi wúrà bò. 22 Ó fi wúrà bo gbogbo ilé náà títí wọ́n fi parí rẹ̀ látòkèdélẹ̀; ó tún fi wúrà bo gbogbo pẹpẹ+ tí ó wà nítòsí yàrá inú lọ́hùn-ún.

23 Nínú yàrá inú lọ́hùn-ún náà, ó fi igi ahóyaya* ṣe kérúbù méjì+ síbẹ̀, gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.+ 24 Ìyẹ́ apá kan kérúbù náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ìyẹ́ apá kejì sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni ó jẹ́ láti ṣóńṣó orí ìyẹ́ apá kan dé ṣóńṣó orí ìyẹ́ apá kejì. 25 Kérúbù kejì náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá. Àwọn kérúbù méjèèjì rí bákan náà, wọn ò sì tóbi ju ara wọn. 26 Gíga kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá bíi ti kérúbù kejì. 27 Lẹ́yìn náà, ó gbé àwọn kérúbù náà+ sínú yàrá inú lọ́hùn-ún.* Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà nà jáde tí ó fi jẹ́ pé ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́ kan ògiri kìíní, ìyẹ́ apá kérúbù kejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá àwọn méjèèjì wá kanra ní àárín ilé náà. 28 Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà.

29 Ó gbẹ́ àwòrán àwọn kérúbù,+ igi ọ̀pẹ+ àti ìtànná òdòdó+ sára gbogbo ògiri yàrá méjèèjì* tó wà nínú ilé náà yí ká. 30 Ó fi wúrà bo ilẹ̀ yàrá méjèèjì tó wà nínú ilé náà. 31 Ó fi igi ahóyaya ṣe ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà yàrá inú lọ́hùn-ún, ó tún fi ṣe àwọn òpó ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àti àwọn òpó ilẹ̀kùn, ó jẹ́ ìdá márùn-ún* ògiri náà. 32 Igi ahóyaya ni wọ́n fi ṣe àwọn ilẹ̀kùn méjèèjì, ó gbẹ́ àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ìtànná òdòdó sára wọn, ó sì fi wúrà bò wọ́n; ó fi òòlù tẹ wúrà náà mọ́ àwọn kérúbù àti àwọn igi ọ̀pẹ náà lára. 33 Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe fi igi ahóyaya ṣe férémù ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì,* igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì dọ́gba.* 34 Ó fi igi júnípà ṣe ilẹ̀kùn méjì. Ilẹ̀kùn àkọ́kọ́ ní awẹ́ méjì tó ṣeé pa dé, ilẹ̀kùn kejì sì ní awẹ́ méjì tó ṣeé pa dé.+ 35 Ó gbẹ́ àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ìtànná òdòdó, ó sì fi wúrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo gbogbo wọn.

36 Ó fi òkúta gbígbẹ́ kọ́ ipele mẹ́ta ògiri àgbàlá inú,+ lẹ́yìn náà wọ́n gbé ipele kan ìtì igi kédárì+ lé e.

37 Ní ọdún kẹrin, oṣù Sífì,* wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀;+ 38 ní ọdún kọkànlá, oṣù Búlì* (ìyẹn, oṣù kẹjọ), wọ́n parí gbogbo iṣẹ́ ilé náà bó ṣe wà nínú àwòrán ilé kíkọ́ rẹ̀.+ Torí náà, ọdún méje ni ó fi kọ́ ọ.

7 Ọdún mẹ́tàlá (13) ló gba Sólómọ́nì láti kọ́ ilé* rẹ̀,+ títí ó fi parí ilé náà látòkèdélẹ̀.+

2 Ó kọ́ Ilé Igbó Lẹ́bánónì,+ gígùn ilé náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́,* fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́, ó kọ́ ọ sórí ọ̀wọ́ mẹ́rin òpó igi kédárì;+ àwọn ìtì igi kédárì sì wà lórí àwọn òpó náà. 3 Wọ́n fi igi kédárì pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí ilé náà lókè, ó wà lórí àwọn ọ̀pá àjà tí ó wà lórí àwọn òpó náà; iye wọn jẹ́ márùndínláàádọ́ta (45), mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ló sì wà nínú ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan. 4 Ọ̀wọ́ mẹ́ta fèrèsé* tó ní férémù ni ó wà, fèrèsé kọ̀ọ̀kan sì dojú kọ fèrèsé míì ní ipele mẹ́ta. 5 Gbogbo ẹnu ọ̀nà àti àwọn òpó ilẹ̀kùn ló ní férémù onígun mẹ́rin tó dọ́gba,* irú férémù yìí náà ló wà ní iwájú àwọn fèrèsé tó dojú kọra tí wọ́n wà ní ipele mẹ́ta.

6 Ó kọ́ Gbọ̀ngàn* Olópòó tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́, ibi àbáwọlé kan sì wà níwájú rẹ̀ tí ó ní àwọn òpó àti ìbòrí.

7 Ó tún kọ́ Gbọ̀ngàn* Ìtẹ́,+ níbi tí yóò ti máa ṣe ìdájọ́, ìyẹn Gbọ̀ngàn Ìdájọ́,+ wọ́n sì fi igi kédárì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ láti ìsàlẹ̀ dé ibi igi ìrólé lókè.

8 Ó kọ́ ilé* tí á máa gbé ní àgbàlá kejì+ sẹ́yìn Gbọ̀ngàn* náà, iṣẹ́ ọnà wọn sì jọra. Ó tún kọ́ ilé kan tí ó dà bíi Gbọ̀ngàn yìí fún ọmọbìnrin Fáráò, ẹni tí Sólómọ́nì fi ṣe aya.+

9 Gbogbo èyí ni a fi òkúta olówó ńlá ṣe,+ tí a sì gbẹ́ bó ṣe wà nínú ìwọ̀n, tí a fi ayùn òkúta rẹ́ nínú àti lóde, láti ìpìlẹ̀ títí dé ìbòrí ògiri àti lóde títí dé àgbàlá ńlá.+ 10 Wọ́n fi àwọn òkúta títóbi, tó jẹ́ olówó ńlá ṣe ìpìlẹ̀ wọn; àwọn òkúta kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, àwọn òkúta míì sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ. 11 Orí wọn ni àwọn òkúta olówó ńlá wà, èyí tí a gbẹ́ bó ṣe wà nínú ìwọ̀n, bẹ́ẹ̀ sì ni igi kédárì. 12 Ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́ kan ìtì igi kédárì yí àgbàlá ńlá náà ká bíi ti àgbàlá inú+ ilé Jèhófà àti ibi àbáwọlé* ilé náà.+

13 Ọba Sólómọ́nì ránṣẹ́ sí Hírámù,+ ó sì wá láti Tírè. 14 Ọmọkùnrin opó kan láti inú ẹ̀yà Náfútálì ni, ará Tírè ni bàbá rẹ̀, alágbẹ̀dẹ bàbà+ sì ni. Hírámù mọṣẹ́ gan-an, ó ní òye,+ ó sì mọ bí wọ́n ṣe ń fi bàbà* ṣe onírúurú nǹkan. Torí náà, ó wá sọ́dọ̀ Ọba Sólómọ́nì, ó sì ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

15 Ó mọ òpó bàbà méjì;+ gíga òpó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún (18), okùn ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjìlá (12) lè yí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òpó náà ká.*+ 16 Ó fi bàbà rọ ọpọ́n méjì sórí àwọn òpó náà. Gíga ọpọ́n kìíní jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga ọpọ́n kejì sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. 17 Ó fi ẹ̀wọ̀n ṣe iṣẹ́ ọnà tó dà bí àwọ̀n sórí ọpọ́n tó wà lórí òpó kọ̀ọ̀kan;+ méje sára ọpọ́n kìíní àti méje sára ọpọ́n kejì. 18 Ó ṣe ìlà méjì pómégíránétì yí àwọ̀n náà ká láti bo ọpọ́n tó wà lórí òpó náà; ohun kan náà ni ó ṣe sí ọpọ́n méjèèjì. 19 Àwọn ọpọ́n tó wà lórí àwọn òpó ibi àbáwọlé* náà ní iṣẹ́ ọnà lára, èyí tó dà bí òdòdó lílì, tí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. 20 Àwọn ọpọ́n náà wà lórí òpó méjì náà, àwọ̀n sì wà lára ibi tó rí rogodo lápá ìsàlẹ̀ ọpọ́n náà; igba (200) pómégíránétì sì wà lórí àwọn ìlà tó yí ọpọ́n kọ̀ọ̀kan ká.+

21 Ó ṣe àwọn òpó ibi àbáwọlé* tẹ́ńpìlì.*+ Ó ṣe òpó apá ọ̀tún,* ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jákínì,* lẹ́yìn náà, ó ṣe òpó apá òsì,* ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bóásì.*+ 22 Iṣẹ́ ọnà tó dà bí òdòdó lílì wà lórí àwọn òpó náà. Bí iṣẹ́ àwọn òpó náà ṣe parí nìyẹn.

23 Lẹ́yìn náà, ó fi irin ṣe Òkun.*+ Ó rí ribiti, fífẹ̀ ẹnu rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, okùn ìdíwọ̀n ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́ ló sì lè yí i ká.*+ 24 Àwọn iṣẹ́ ọnà tó rí bí akèrègbè+ wà nísàlẹ̀ ẹnu rẹ̀ yí ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan, wọ́n yí Òkun náà po, ìlà méjì àwọn iṣẹ́ ọnà tó rí bí akèrègbè náà ni ó ṣe mọ́ ọn lára. 25 Wọ́n gbé Òkun náà ka orí akọ màlúù méjìlá (12),+ mẹ́ta dojú kọ àríwá, mẹ́ta dojú kọ ìwọ̀ oòrùn, mẹ́ta dojú kọ gúúsù, mẹ́ta sì dojú kọ ìlà oòrùn; Òkun náà wà lórí wọn, gbogbo wọn sì kọ̀dí sí abẹ́ Òkun náà. 26 Ìnípọn rẹ̀ jẹ́ ìbú ọwọ́ kan;* ẹnu rẹ̀ sì dà bí ẹnu ife, bí ìtànná òdòdó lílì. Ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) báàtì* ni ó ń gbà.

27 Ó fi bàbà ṣe kẹ̀kẹ́ ẹrù*+ mẹ́wàá. Gígùn kẹ̀kẹ́ ẹrù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta. 28 Bí wọ́n ṣe ṣe àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù náà nìyí: Wọ́n ní àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́, àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ náà sì wà láàárín àwọn ọ̀pá ìdábùú. 29 Àwọn kìnnìún,+ akọ màlúù àti kérúbù+ sì wà lára àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ tó wà láàárín àwọn ọ̀pá ìdábùú náà, iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ kan náà ló wà lára àwọn ọ̀pá ìdábùú náà. Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tó so kọ́ra wà lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún àti àwọn akọ màlúù náà. 30 Kẹ̀kẹ́ ẹrù kọ̀ọ̀kan ní àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rin tí a fi bàbà ṣe àti àwọn ọ̀pá àgbá kẹ̀kẹ́ tí a fi bàbà ṣe, ọ̀pá igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jẹ́ agbóhunró. Bàsíà náà wà lórí àwọn agbóhunró tí a ṣe ohun ọ̀ṣọ́ tó so kọ́ra mọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́. 31 Ohun ọ̀ṣọ́ tó dà bí adé wà ní ibi ẹnu bàsíà náà, láti ìdí bàsíà náà sókè jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan; ẹnu kẹ̀kẹ́ ẹrù náà rí ribiti, gíga ẹnu náà lápapọ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀, wọ́n fín iṣẹ́ ọnà sí ibi ẹnu rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní igun mẹ́rin tó dọ́gba, wọn kò rí ribiti. 32 Àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà nísàlẹ̀ àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ náà, wọ́n so ọ̀pá igun àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà mọ́ kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, gíga àgbá kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀. 33 Wọ́n ṣe àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà bí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin. Irin ni wọ́n fi rọ gbogbo ọ̀pá igun wọn, ríìmù wọn, sípóòkù wọn àti họ́ọ̀bù wọn. 34 Agbóhunró mẹ́rin ló wà lára igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kẹ̀kẹ́ ẹrù kọ̀ọ̀kan; wọ́n ṣe àwọn agbóhunró náà mọ́ ara* kẹ̀kẹ́ ẹrù náà. 35 Ohun ọ̀ṣọ́ to ṣe ribiti wà lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, gíga rẹ̀ jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, àwọn férémù kéékèèké àti àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni a ṣe mọ́* ara rẹ̀. 36 Ó fín àwọn kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ sára àwọn férémù kéékèèké àti sára àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ bí àyè tó wà lára ọ̀kọ̀ọ̀kan ṣe fẹ̀ tó, ó sì ṣe ohun ọ̀ṣọ́ tó so kọ́ra yí i ká.+ 37 Bí ó ti ṣe kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá+ náà nìyẹn; bákan náà ni ó rọ gbogbo wọn,+ ìwọ̀n kan náà ni wọ́n, bákan náà ni wọ́n sì rí.

38 Ó ṣe bàsíà bàbà+ mẹ́wàá; ogójì (40) òṣùwọ̀n báàtì ni bàsíà kọ̀ọ̀kan ń gbà. Ìwọ̀n bàsíà kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin.* Kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ní bàsíà kọ̀ọ̀kan lórí. 39 Lẹ́yìn náà, ó gbé kẹ̀kẹ́ ẹrù márùn-ún sí apá ọ̀tún ilé náà àti márùn-ún sí apá òsì ilé náà, ó sì gbé Òkun náà sí apá ọ̀tún ilé náà láàárín gúúsù àti ìlà oòrùn.+

40 Hírámù+ tún ṣe àwọn bàsíà, àwọn ṣọ́bìrì+ àti àwọn abọ́.+ Bẹ́ẹ̀ ni Hírámù parí gbogbo iṣẹ́ ilé Jèhófà+ tó ṣe fún Ọba Sólómọ́nì, ìyẹn: 41 àwọn òpó méjèèjì+ àti àwọn ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí òpó méjèèjì; iṣẹ́ ọnà méjèèjì+ tó dà bí àwọ̀n tó fi bo ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí àwọn òpó náà; 42 ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) pómégíránétì+ fún iṣẹ́ ọnà méjì tó dà bí àwọ̀n, ìlà méjì pómégíránétì fún iṣẹ́ ọnà kọ̀ọ̀kan tó dà bí àwọ̀n, tó fi bo ọpọ́n méjèèjì tó rí bí abọ́ lórí òpó méjèèjì; 43 kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá+ àti bàsíà mẹ́wẹ̀ẹ̀wá+ tó wà lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù náà; 44 Òkun náà+ àti akọ màlúù méjìlá (12) tó wà lábẹ́ Òkun náà; 45 àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn abọ́ àti gbogbo àwọn nǹkan èlò tí Hírámù fi bàbà dídán ṣe fún Ọba Sólómọ́nì fún ilé Jèhófà. 46 Agbègbè Jọ́dánì ni ọba ti rọ wọ́n nínú ohun tó fi amọ̀ ṣe, láàárín Súkótù àti Sárétánì.

47 Sólómọ́nì fi gbogbo nǹkan èlò náà sílẹ̀ láìwọ̀n wọ́n nítorí wọ́n ti pọ̀ jù. A kò mọ bí ìwọ̀n bàbà náà ṣe pọ̀ tó.+ 48 Sólómọ́nì ṣe gbogbo nǹkan èlò ilé Jèhófà, àwọn ni: pẹpẹ+ wúrà; tábìlì wúrà+ tí wọ́n á máa kó búrẹ́dì àfihàn sí; 49 àwọn ọ̀pá fìtílà+ tí a fi ògidì wúrà ṣe, márùn-ún lápá ọ̀tún àti márùn-ún lápá òsì níwájú yàrá inú lọ́hùn-ún; àwọn ìtànná òdòdó,+ àwọn fìtílà àti àwọn ìpaná* tí a fi wúrà ṣe;+ 50 àwọn bàsíà, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà,+ àwọn abọ́, àwọn ife+ àti àwọn ìkóná+ tí á fi ògidì wúrà ṣe; ihò àwọn ilẹ̀kùn ilé inú lọ́hùn-ún,+ ìyẹn, Ibi Mímọ́ Jù Lọ àti ihò àwọn ilẹ̀kùn ilé tẹ́ńpìlì+ tí a fi wúrà ṣe.

51 Torí náà, Ọba Sólómọ́nì parí gbogbo iṣẹ́ ilé Jèhófà tó yẹ ní ṣíṣe. Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì kó àwọn ohun tí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́+ wọlé, ó kó fàdákà, wúrà àti àwọn ohun èlò wá sínú ibi tí wọ́n ń kó ìṣúra sí ní ilé Jèhófà.+

8 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ,+ gbogbo olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí agbo ilé ní Ísírẹ́lì.+ Wọ́n wá sọ́dọ̀ Ọba Sólómọ́nì ní Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti Ìlú Dáfídì,+ ìyẹn Síónì.+ 2 Gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì pé jọ síwájú Ọba Sólómọ́nì nígbà àjọyọ̀* ní oṣù Étánímù,* ìyẹn oṣù keje.+ 3 Nítorí náà, gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì wá, àwọn àlùfáà sì gbé Àpótí náà.+ 4 Wọ́n gbé Àpótí Jèhófà wá àti àgọ́ ìpàdé+ pẹ̀lú gbogbo nǹkan èlò mímọ́ tó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ló gbé wọn wá. 5 Ọba Sólómọ́nì àti gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì, ìyẹn àwọn tó ní kí wọ́n pàdé òun, wà níwájú Àpótí náà. Àgùntàn àti màlúù tí wọ́n fi rúbọ+ pọ̀ débi pé wọn ò ṣeé kà, wọn ò sì níye.

6 Nígbà náà, àwọn àlùfáà gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà wá sí àyè rẹ̀,+ ní yàrá inú lọ́hùn-ún ilé náà, ìyẹn Ibi Mímọ́ Jù Lọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ apá àwọn kérúbù.+

7 Torí náà, ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà nà jáde sórí ibi tí Àpótí náà wà, tó fi jẹ́ pé àwọn kérúbù náà ṣíji bo Àpótí náà àti àwọn ọ̀pá rẹ̀.+ 8 Àwọn ọ̀pá+ náà gùn débi pé a lè rí orí wọn láti Ibi Mímọ́ ní iwájú yàrá inú lọ́hùn-ún, ṣùgbọ́n a kò lè rí wọn láti òde. Wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí. 9 Kò sí nǹkan míì nínú Àpótí náà àfi wàláà òkúta méjì+ tí Mósè kó síbẹ̀+ ní Hórébù, nígbà tí Jèhófà bá àwọn èèyàn Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú+ bí wọ́n ṣe ń jáde bọ̀ láti ilẹ̀ Íjíbítì.+

10 Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti ibi mímọ́, ìkùukùu+ kún ilé Jèhófà.+ 11 Àwọn àlùfáà kò lè dúró ṣe iṣẹ́ wọn nítorí ìkùukùu náà, torí pé ògo Jèhófà kún ilé Jèhófà.+ 12 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì sọ̀rọ̀, ó ní: “Jèhófà sọ pé inú ìṣúdùdù tó kàmàmà+ ni òun á máa gbé. 13 Mo ti kọ́ ilé ológo kan parí fún ọ, ibi tó fìdí múlẹ̀ tí wàá máa gbé títí láé.”+

14 Lẹ́yìn náà, ọba yíjú pa dà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í súre fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, bí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì ṣe wà ní ìdúró.+ 15 Ó sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó fi ẹnu ara rẹ̀ ṣèlérí fún Dáfídì bàbá mi, tó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un ṣẹ, tó sọ pé, 16 ‘Láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì, mi ò yan ìlú kankan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí màá kọ́ ilé sí fún orúkọ mi, kí ó lè máa wà níbẹ̀,+ ṣùgbọ́n mo ti yan Dáfídì láti ṣe olórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’ 17 Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn Dáfídì bàbá mi pé kí ó kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 18 Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Dáfídì bàbá mi pé, ‘Ìfẹ́ ọkàn rẹ ni pé kí o kọ́ ilé fún orúkọ mi, ó sì dára bó ṣe ń wù ọ́ yìí. 19 Àmọ́, ìwọ kọ́ ló máa kọ́ ilé náà, ọmọ tí o máa bí* ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.’+ 20 Jèhófà ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, torí mo ti jọba ní ipò Dáfídì bàbá mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, bí Jèhófà ti ṣèlérí. Mo tún kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ 21 mo sì ṣe àyè kan síbẹ̀ fún Àpótí tí májẹ̀mú+ Jèhófà wà nínú rẹ̀, èyí tó bá àwọn baba ńlá wa dá nígbà tó ń mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”

22 Sólómọ́nì wá dúró níwájú pẹpẹ Jèhófà ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀run,+ 23 ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tó dà bí rẹ+ ní ọ̀run lókè tàbí lórí ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀, ò ń pa májẹ̀mú mọ́, o sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀+ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tó ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ.+ 24 O ti mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ. Ẹnu rẹ lo fi ṣe ìlérí náà, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú un ṣẹ lónìí yìí.+ 25 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ, nígbà tí o sọ pé: ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ níwájú mi tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, bí àwọn ọmọ rẹ bá ṣáà ti ń fiyè sí ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì ń rìn níwájú mi bí ìwọ náà ṣe rìn níwájú mi.’+ 26 Ní báyìí, ìwọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jọ̀wọ́ mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ.

27 “Àmọ́, ṣé Ọlọ́run máa gbé inú ayé ni?+ Wò ó! Àwọn ọ̀run, àní, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́;+ ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ilé tí mo kọ́ yìí!+ 28 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi, fiyè sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, kí o sì fetí sí igbe ìránṣẹ́ rẹ fún ìrànlọ́wọ́ àti àdúrà tó ń gbà níwájú rẹ lónìí. 29 Kí ojú rẹ wà lára ilé yìí tọ̀sántòru, lára ibi tí o sọ pé, ‘Orúkọ mi yóò wà níbẹ̀,’+ láti fetí sí àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní ìdojúkọ ibí yìí.+ 30 Kí o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ fún ojú rere àti ẹ̀bẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń sọ nínú àdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí; kí o gbọ́ láti ibi tí ò ń gbé ní ọ̀run;+ kí o gbọ́, kí o sì dárí jì wọ́n.+

31 “Nígbà tí ẹnì kan bá ṣẹ ọmọnìkejì rẹ̀, tó mú kó búra,* tó sì mú kó wà lábẹ́ ìbúra* náà, tó bá wá síwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí nígbà tó ṣì wà lábẹ́ ìbúra* náà,+ 32 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o gbé ìgbésẹ̀, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kí o pe ẹni burúkú ní ẹlẹ́bi,* kí o sì jẹ́ kí ohun tó ṣe dà lé e lórí, kí o pe olódodo ní aláìṣẹ̀,* kí o sì san èrè òdodo rẹ̀ fún un.+

33 “Nígbà tí ọ̀tá bá ṣẹ́gun àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n wá pa dà sọ́dọ̀ rẹ, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga,+ tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀ ọ́ nínú ilé yìí pé kí o ṣojú rere sí àwọn,+ 34 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì jì wọ́n, kí o sì mú wọn pa dà wá sí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn.+

35 “Nígbà tí ọ̀run bá sé pa, tí òjò kò sì rọ̀+ torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga, tí wọ́n sì yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé o rẹ̀ wọ́n wálẹ̀,*+ 36 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, ìyẹn àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé wàá tọ́ wọn sí ọ̀nà+ tó yẹ kí wọ́n máa rìn; kí o sì rọ̀jò sórí ilẹ̀ rẹ+ tí o fún àwọn èèyàn rẹ láti jogún.

37 “Bí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ náà+ tàbí tí àjàkálẹ̀ àrùn bá jà, tí ooru tó ń jó ewéko gbẹ tàbí èbíbu+ bá wà, tí ọ̀wọ́ eéṣú tàbí ọ̀yánnú eéṣú* bá wà tàbí tí ọ̀tá wọn bá dó tì wọ́n ní ìlú èyíkéyìí ní ilẹ̀ náà* tàbí tí ìyọnu èyíkéyìí tàbí àrùn bá wáyé,+ 38 àdúrà èyíkéyìí tí ì báà jẹ́, ìbéèrè fún ojú rere+ èyíkéyìí tí ẹnikẹ́ni bá béèrè tàbí èyí tí gbogbo àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì bá béèrè (nítorí pé kálukú ló mọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀),+ tí wọ́n bá tẹ́ ọwọ́ wọn sí apá ibi tí ilé yìí wà, 39 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé,+ kí o dárí jì wọ́n,+ kí o sì gbé ìgbésẹ̀; kí o san èrè fún kálukú gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ nítorí pé o mọ ọkàn rẹ̀ (ìwọ nìkan lo mọ ọkàn gbogbo èèyàn lóòótọ́),+ 40 kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n á fi gbé lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wa.

41 “Bákan náà, ní ti àjèjì tí kì í ṣe ara àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, àmọ́ tó wá láti ilẹ̀ tó jìnnà nítorí orúkọ rẹ*+ 42 (nítorí wọ́n máa gbọ́ nípa orúkọ ńlá rẹ+ àti nípa ọwọ́ agbára rẹ pẹ̀lú apá rẹ tó nà jáde), tí ó sì wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ilé yìí, 43 nígbà náà, kí o fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé,+ kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo aráyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ,+ bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì ti ń ṣe, kí wọ́n sì mọ̀ pé a ti fi orúkọ rẹ pe ilé tí mo kọ́ yìí.

44 “Tí àwọn èèyàn rẹ bá lọ bá ọ̀tá wọn jà lójú ogun bí o ṣe rán wọn,+ tí wọ́n sì gbàdúrà+ sí Jèhófà ní ìdojúkọ ìlú tí o yàn+ àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+ 45 nígbà náà, kí o gbọ́ àdúrà wọn láti ọ̀run àti ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí o ṣojú rere sí àwọn, kí o sì ṣe ìdájọ́ nítorí wọn.

46 “Tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí kò sí èèyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀),+ tí inú rẹ ru sí wọn, tí o fi wọ́n sílẹ̀ fún ọ̀tá, tí àwọn tó mú wọn sì kó wọn lẹ́rú lọ si ilẹ̀ ọ̀tá, bóyá èyí tó jìnnà tàbí èyí tó wà nítòsí;+ 47 tí wọ́n bá ro inú ara wọn wò ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ,+ tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ,+ tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o ṣojú rere sí àwọn ní ilẹ̀ àwọn tó mú wọn lẹ́rú,+ tí wọ́n sọ pé, ‘A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣàṣìṣe; a ti ṣe ohun búburú,’+ 48 tí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn+ àti gbogbo ara* wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá tó kó wọn lọ sóko ẹrú, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ ní ìdojúkọ ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn àti ìlú tí o yàn àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+ 49 nígbà náà, láti ibi tí ò ń gbé ní ọ̀run,+ kí o gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí o ṣojú rere sí àwọn, kí o sì ṣe ìdájọ́ nítorí wọn, 50 kí o dárí ji àwọn èèyàn rẹ tó ṣẹ̀ ọ́, kí o dárí gbogbo bí wọ́n ṣe tẹ ìlànà rẹ lójú jì wọ́n. Kí o jẹ́ kí wọ́n rójú àánú àwọn tó kó wọn lẹ́rú, kí wọ́n sì ṣàánú wọn+ 51 (nítorí èèyàn rẹ àti ogún rẹ ni wọ́n,+ àwọn tí o mú jáde kúrò ní Íjíbítì,+ láti ibi iná tí a fi ń yọ́ irin).+ 52 Kí o ṣí ojú rẹ sí ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ pé kí o ṣojú rere sí òun+ àti sí ẹ̀bẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì pé kí o ṣojú rere sí àwọn, kí o máa fetí sí wọn nígbàkigbà tí wọ́n bá ké pè ọ́.*+ 53 Nítorí o ti yà wọ́n sọ́tọ̀ láti jẹ́ ogún rẹ nínú gbogbo aráyé,+ bí o ṣe gba ẹnu Mósè ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, nígbà tí ò ń mú àwọn baba ńlá wa jáde kúrò ní Íjíbítì, ìwọ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”

54 Gbàrà tí Sólómọ́nì parí gbogbo àdúrà yìí sí Jèhófà àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, ó dìde kúrò níwájú pẹpẹ Jèhófà, níbi tí ó kúnlẹ̀ sí, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀run.+ 55 Ó dúró, ó gbóhùn sókè, ó sì súre fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó ní: 56 “Ìyìn ni fún Jèhófà, tí ó fún àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì ní ibi ìsinmi bí ó ti ṣèlérí.+ Kò sí ìkankan nínú gbogbo ìlérí tí ó ṣe nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó lọ láìṣẹ.+ 57 Kí Jèhófà Ọlọ́run wa wà pẹ̀lú wa, bí ó ṣe wà pẹ̀lú àwọn baba ńlá wa.+ Kí ó má ṣe fi wá sílẹ̀, kí ó má sì pa wá tì.+ 58 Kí ó mú kí ọkàn wa máa fà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,+ kí a lè máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, kí a sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, àwọn ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ tí ó pa láṣẹ pé kí àwọn baba ńlá wa máa pa mọ́. 59 Kí àwọn ọ̀rọ̀ tí mo fi bẹ Jèhófà fún ojú rere máa wà lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa tọ̀sántòru, kí ó lè máa ṣe ìdájọ́ nítorí ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bá ṣe gbà, 60 kí gbogbo aráyé lè mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.+ Kò sí ẹlòmíì!+ 61 Torí náà, ẹ fi gbogbo ọkàn yín+ sin Jèhófà Ọlọ́run wa láti máa rìn nínú àwọn ìlànà rẹ̀ àti láti máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ bíi ti òní yìí.”

62 Ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ wá rú ẹbọ púpọ̀ níwájú Jèhófà.+ 63 Sólómọ́nì rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ sí Jèhófà: Ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) màlúù àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn ni ó fi rúbọ. Bí ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣayẹyẹ ṣíṣí ilé Jèhófà+ nìyẹn. 64 Ní ọjọ́ yẹn, ọba ní láti ya àárín àgbàlá tó wà níwájú ilé Jèhófà sí mímọ́, torí ibẹ̀ ló ti máa rú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà pẹ̀lú àwọn apá tó lọ́ràá lára àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀, nítorí pé pẹpẹ bàbà+ tó wà níwájú Jèhófà kéré ju ohun tó lè gba àwọn ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà pẹ̀lú àwọn apá tó lọ́ràá+ lára àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀. 65 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì ṣe àjọyọ̀+ náà pẹ̀lú gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n jẹ́ ìjọ ńlá láti Lebo-hámátì* títí dé Àfonífojì Íjíbítì,+ wọ́n wà níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa fún ọjọ́ méje àti ọjọ́ méje míì, ó jẹ́ ọjọ́ mẹ́rìnlá (14) lápapọ̀. 66 Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e,* ó ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn, inú wọn ń dùn, ayọ̀ sì kún ọkàn wọn nítorí gbogbo oore+ tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Ísírẹ́lì àwọn èèyàn rẹ̀.

9 Gbàrà tí Sólómọ́nì parí kíkọ́ ilé Jèhófà àti ilé* ọba+ àti gbogbo ohun tó wu Sólómọ́nì láti ṣe,+ 2 Jèhófà wá fara han Sólómọ́nì nígbà kejì, bó ṣe fara hàn án ní Gíbíónì.+ 3 Jèhófà sọ fún un pé: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ àti ẹ̀bẹ̀ tí o bẹ̀ fún ojú rere níwájú mi. Mo ti ya ilé tí o kọ́ yìí sí mímọ́ torí mo ti fi orúkọ mi síbẹ̀ títí lọ,+ ojú mi àti ọkàn mi á sì máa wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.+ 4 Ní tìrẹ, tí o bá rìn níwájú mi bí Dáfídì bàbá rẹ ṣe rìn+ pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn+ àti ìdúróṣinṣin,+ tí ò ń ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ,+ tí o sì ń pa àwọn ìlànà mi àti àwọn ìdájọ́ mi mọ́,+ 5 ìgbà náà ni màá fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ lórí Ísírẹ́lì múlẹ̀ títí láé, bí mo ti ṣèlérí fún Dáfídì bàbá rẹ pé, ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’+ 6 Àmọ́ tí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín bá pa dà lẹ́yìn mi, tí ẹ kò sì pa àwọn àṣẹ àti òfin tí mo fún yín mọ́, tí ẹ wá lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ sì ń forí balẹ̀ fún wọn,+ 7 ṣe ni màá ké Ísírẹ́lì kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ màá gbé ilé tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sọ nù kúrò níwájú mi,+ Ísírẹ́lì yóò sì di ẹni ẹ̀gàn* àti ẹni ẹ̀sín láàárín gbogbo èèyàn.+ 8 Ilé yìí á di àwókù.+ Gbogbo ẹni tó bá gba ibẹ̀ kọjá á wò ó tìyanutìyanu, á súfèé, á sì sọ pé, ‘Kì nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+ 9 Nígbà náà, wọ́n á sọ pé, ‘Torí pé wọ́n fi Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀ ni, ẹni tó mú àwọn baba ńlá wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n yíjú sí àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mú gbogbo àjálù yìí bá wọn.’”+

10 Ní òpin ogún (20) ọdún tí Sólómọ́nì fi kọ́ ilé méjèèjì, ìyẹn ilé Jèhófà àti ilé* ọba,+ 11 Hírámù+ ọba Tírè fún Sólómọ́nì ní àwọn gẹdú igi kédárì àti ti júnípà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ wúrà tí ó béèrè,+ Ọba Sólómọ́nì sì fún Hírámù ní ogún (20) ìlú ní ilẹ̀ Gálílì. 12 Torí náà, Hírámù jáde kúrò ní Tírè láti lọ wo àwọn ìlú tí Sólómọ́nì fún un, àmọ́ wọn kò tẹ́ ẹ lọ́rùn.* 13 Ó sọ pé: “Irú àwọn ìlú wo ni o fún mi yìí, arákùnrin mi?” Torí náà, Ilẹ̀ Kábúlù* ni à ń pè wọ́n títí di òní yìí. 14 Ní àkókò yẹn, Hírámù fi ọgọ́fà (120) tálẹ́ńtì* wúrà+ ránṣẹ́ sí ọba.

15 Èyí ni ìròyìn nípa àwọn tí Ọba Sólómọ́nì ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun+ láti kọ́ ilé Jèhófà,+ ilé* tirẹ̀, Òkìtì,*+ ògiri Jerúsálẹ́mù, Hásórì,+ Mẹ́gídò+ àti Gésérì.+ 16 (Fáráò ọba Íjíbítì ti wá gba Gésérì, ó dáná sun ún, ó sì pa àwọn ọmọ Kénáánì+ tó ń gbé ìlú náà. Nítorí náà, ó fi ṣe ẹ̀bùn ìdágbére* fún ọmọbìnrin rẹ̀,+ aya Sólómọ́nì.) 17 Sólómọ́nì kọ́* Gésérì, Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀,+ 18 Báálátì+ àti Támárì ní aginjù, ó kọ́ wọn sórí ilẹ̀ náà, 19 Sólómọ́nì tún kọ́ gbogbo àwọn ìlú tó ń kó nǹkan pa mọ́ sí, àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ àwọn ìlú àwọn agẹṣin àti ohunkóhun tó wu Sólómọ́nì láti kọ́ sí Jerúsálẹ́mù, sí Lẹ́bánónì àti sí gbogbo ilẹ̀ tó ń ṣàkóso lé lórí. 20 Ní ti gbogbo èèyàn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ tí wọn kì í ṣe ara àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,+ 21 àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè pa run, Sólómọ́nì ní kí wọ́n máa ṣíṣẹ́ fún òun bí ẹrú títí di òní yìí.+ 22 Àmọ́ Sólómọ́nì kò fi ọmọ Ísírẹ́lì kankan ṣe ẹrú,+ àwọn ló fi ṣe jagunjagun, ìránṣẹ́, ìjòyè, olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun, olórí àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ti àwọn agẹṣin rẹ̀. 23 Ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé àádọ́ta (550) olórí àwọn alábòójútó ló ń darí iṣẹ́ Sólómọ́nì, àwọn ló sì ń darí àwọn òṣìṣẹ́.+

24 Ọmọbìnrin Fáráò+ wá láti Ìlú Dáfídì+ sí ilé tirẹ̀ tí Sólómọ́nì kọ́ fún un; lẹ́yìn náà ó mọ Òkìtì.*+

25 Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún+ ni Sólómọ́nì máa ń rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ lórí pẹpẹ tó mọ fún Jèhófà,+ ó tún ń mú ẹbọ rú èéfín lórí pẹpẹ náà, tí ó wà níwájú Jèhófà. Bí ó sì ṣe parí ilé náà nìyẹn.+

26 Ọba Sólómọ́nì tún ṣe ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun ní Esioni-gébérì,+ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Élótì, ní èbúté Òkun Pupa ní ilẹ̀ Édómù.+ 27 Hírámù kó ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun+ rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òkun tó mọṣẹ́, láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì. 28 Wọ́n lọ sí Ófírì,+ wọ́n sì kó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ogún (420) tálẹ́ńtì wúrà láti ibẹ̀ wá fún Ọba Sólómọ́nì.

10 Nígbà náà, ọbabìnrin Ṣébà gbọ́ bí ìròyìn Sólómọ́nì ṣe ń gbé ògo orúkọ Jèhófà yọ,+ torí náà, ó wá láti fi àwọn ìbéèrè* tó ta kókó dán an wò.+ 2 Ó dé Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn abọ́barìn* tó gbayì,+ pẹ̀lú àwọn ràkúnmí tó ru òróró básámù+ àti wúrà tó pọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye. Ó lọ sọ́dọ̀ Sólómọ́nì, ó sì bá a sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. 3 Sólómọ́nì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Kò sí ohun tó ṣòro* fún ọba láti ṣàlàyé fún un.

4 Nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà rí gbogbo ọgbọ́n Sólómọ́nì+ àti ilé tó kọ́,+ 5 oúnjẹ orí tábìlì rẹ̀,+ bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń jókòó, bó ṣe ṣètò iṣẹ́ àwọn tó ń gbé oúnjẹ fún un àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, àwọn agbọ́tí rẹ̀ àti àwọn ẹbọ sísun tó ń rú déédéé ní ilé Jèhófà, ẹnu yà á gan-an.* 6 Nítorí náà, ó sọ fún ọba pé: “Òótọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ilẹ̀ mi nípa àwọn àṣeyọrí* rẹ àti ọgbọ́n rẹ. 7 Àmọ́ mi ò gba ìròyìn náà gbọ́ títí mo fi wá fojú ara mi rí i. Wò ó! Ohun tí mo gbọ́ kò tiẹ̀ tó ìdajì rárá. Ọgbọ́n rẹ àti aásìkí rẹ kọjá àwọn ohun tí mo gbọ́. 8 Aláyọ̀ ni àwọn èèyàn rẹ, aláyọ̀ sì ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fetí sí ọgbọ́n rẹ!+ 9 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí ọ tí ó fi gbé ọ gorí ìtẹ́ Ísírẹ́lì. Nítorí ìfẹ́ àìnípẹ̀kun tí Jèhófà ní sí Ísírẹ́lì, ó fi ọ́ jọba láti máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ àti láti máa ṣe òdodo.”

10 Lẹ́yìn náà, ó fún ọba ní ọgọ́fà (120) tálẹ́ńtì* wúrà àti òróró básámù+ tó pọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye.+ Kò tún sẹ́ni tó kó irú òróró básámù tó pọ̀ wọlé bí èyí tí ọbabìnrin Ṣébà kó wá fún Ọba Sólómọ́nì.

11 Ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun tí Hírámù fi kó wúrà láti Ófírì+ tún kó àwọn gẹdú igi álígọ́mù+ tó pọ̀ gan-an wá àti àwọn òkúta iyebíye.+ 12 Ọba fi àwọn gẹdú igi álígọ́mù náà ṣe àwọn òpó fún ilé Jèhófà àti fún ilé* ọba, títí kan àwọn háàpù àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín fún àwọn akọrin.+ Wọn ò tún kó irú igi álígọ́mù bẹ́ẹ̀ wọlé mọ́, a kò sì rí irú rẹ̀ mọ́ títí di òní yìí.

13 Ọba Sólómọ́nì náà fún ọbabìnrin Ṣébà ní gbogbo ohun tó fẹ́ àti ohun tó béèrè, yàtọ̀ síyẹn, Sólómọ́nì fúnra rẹ̀ tún fún un láwọn nǹkan míì.* Lẹ́yìn náà, ó kúrò níbẹ̀, ó sì pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+

14 Ìwọ̀n wúrà tí wọ́n ń kó wá fún Sólómọ́nì lọ́dọọdún jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgọ́ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ńtì wúrà,+ 15 yàtọ̀ sí èyí tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti èrè látọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́jà àti látọ̀dọ̀ gbogbo ọba àwọn ará Arébíà àti àwọn gómìnà ilẹ̀ náà.

16 Ọba Sólómọ́nì fi àyọ́pọ̀ wúrà ṣe igba (200) apata ńlá,+ (ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ṣékélì* wúrà ni ó lò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn),+ 17 ó sì fi àyọ́pọ̀ wúrà ṣe ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) asà* (wúrà mínà* mẹ́ta ni ó lò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn). Lẹ́yìn náà, ọba kó wọn sínú Ilé Igbó Lẹ́bánónì.+

18 Ọba tún fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan,+ ó sì fi wúrà tí a yọ́ mọ́ bò ó.+ 19 Àtẹ̀gùn mẹ́fà ni ìtẹ́ náà ní, ó tún ní ìbòrí ribiti kan lẹ́yìn, ibi ìgbápálé wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ìjókòó náà, ère kìnnìún+ kọ̀ọ̀kan sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ibi ìgbápálé náà. 20 Àwọn kìnnìún tó dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́fà náà jẹ́ méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní eteetí àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan. Kò sí ìjọba kankan tó ṣe irú rẹ̀ rí.

21 Gbogbo ohun èlò tí Ọba Sólómọ́nì fi ń mu nǹkan jẹ́ wúrà, gbogbo ohun èlò Ilé Igbó Lẹ́bánónì+ sì jẹ́ ògidì wúrà. Kò sí ìkankan tí wọ́n fi fàdákà ṣe, nítorí fàdákà kò já mọ́ nǹkan kan nígbà ayé Sólómọ́nì.+ 22 Ọba ní ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+ lórí òkun pẹ̀lú ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun ti Hírámù. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹ́ta ni ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun Táṣíṣì máa ń kó wúrà àti fàdákà, eyín erin,+ àwọn ìnàkí àti àwọn ẹyẹ ọ̀kín wọlé.

23 Nítorí náà, ọrọ̀+ àti ọgbọ́n+ Ọba Sólómọ́nì pọ̀ ju ti gbogbo àwọn ọba yòókù láyé. 24 Àwọn èèyàn láti ibi gbogbo láyé ń wá sọ́dọ̀* Sólómọ́nì kí wọ́n lè gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run fi sí i lọ́kàn.+ 25 Kálukú wọn ń mú ẹ̀bùn wá, ìyẹn àwọn ohun èlò fàdákà, àwọn ohun èlò wúrà, àwọn aṣọ, ìhámọ́ra, òróró básámù, àwọn ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* wọ́n sì ń mú wọn wá lọ́dọọdún.

26 Sólómọ́nì sì ń kó kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin* jọ; ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (1,400) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin,*+ ó sì kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.+

27 Ọba mú kí fàdákà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pọ̀ rẹpẹtẹ bí òkúta, ó sì mú kí igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là.+

28 Íjíbítì ni wọ́n ti ń kó àwọn ẹṣin wá fún Sólómọ́nì, àwùjọ àwọn oníṣòwò ọba á sì ra agbo ẹṣin* náà ní iye kan.+ 29 Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) fàdákà ni wọ́n ń ra kẹ̀kẹ́ ẹṣin kọ̀ọ̀kan láti Íjíbítì, àádọ́jọ (150) fàdákà sì ni wọ́n ń ra ẹṣin kọ̀ọ̀kan; wọ́n á wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo ọba àwọn ọmọ Hétì+ àti àwọn ọba Síríà.

11 Àmọ́ Ọba Sólómọ́nì nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin ilẹ̀ àjèjì,+ yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Fáráò,+ àwọn tó tún nífẹ̀ẹ́ ni: àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ Móábù,+ ọmọ Ámónì,+ ọmọ Édómù, ọmọ Sídónì+ àti ọmọ Hétì.+ 2 Wọ́n wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ lọ sí àárín wọn,* wọn ò sì gbọ́dọ̀ wá sí àárín yín, torí ó dájú pé wọ́n á mú kí ọkàn yín fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run wọn.”+ Àmọ́ ọkàn Sólómọ́nì kò kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. 3 Ó ní ọgọ́rùn-ún méje (700) ìyàwó tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọba àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) wáhàrì,* ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìyàwó rẹ̀ yí i lọ́kàn pa dà.* 4 Nígbà tí Sólómọ́nì darúgbó,+ àwọn ìyàwó rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run míì,+ kò sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bíi Dáfídì bàbá rẹ̀. 5 Sólómọ́nì yíjú sí Áṣítórétì,+ abo ọlọ́run àwọn ọmọ Sídónì àti Mílíkómù,+ ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Ámónì. 6 Sólómọ́nì ṣe ohun tí ó burú lójú Jèhófà, kò sì tẹ̀ lé Jèhófà délẹ̀délẹ̀* bí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti ṣe.+

7 Ìgbà náà ni Sólómọ́nì kọ́ ibi gíga+ kan fún Kémóṣì, ọlọ́run ìríra Móábù, lórí òkè tó wà níwájú Jerúsálẹ́mù, ó sì tún kọ́ òmíràn fún Mólékì,+ ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Ámónì.+ 8 Ohun tí ó ṣe fún gbogbo ìyàwó ilẹ̀ àjèjì tó fẹ́ nìyẹn, àwọn tó ń mú ẹbọ rú èéfín, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn.

9 Inú bí Jèhófà gan-an sí Sólómọ́nì, nítorí ọkàn rẹ̀ ti kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ ẹni tó fara hàn án lẹ́ẹ̀mejì,+ 10 tí ó sì kìlọ̀ fún un nípa nǹkan yìí pé kí ó má ṣe tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì.+ Àmọ́ kò ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ. 11 Jèhófà wá sọ fún Sólómọ́nì pé: “Nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò pa májẹ̀mú mi àti òfin mi mọ́, bí mo ṣe pa á láṣẹ fún ọ, màá rí i dájú pé mo fa ìjọba náà ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, màá sì fún ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ.+ 12 Àmọ́, nítorí Dáfídì bàbá rẹ, mi ò ní ṣe èyí nígbà ayé rẹ. Ọwọ́ ọmọ rẹ ni màá ti fà á ya,+ 13 àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìjọba náà+ ni màá fà ya. Màá fún ọmọ rẹ ní ẹ̀yà kan,+ nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti nítorí Jerúsálẹ́mù tí mo yàn.”+

14 Lẹ́yìn náà, Jèhófà gbé alátakò kan dìde sí Sólómọ́nì,+ ìyẹn Hádádì ọmọ Édómù, láti ìdílé ọba Édómù.+ 15 Nígbà tí Dáfídì ṣẹ́gun Édómù,+ Jóábù olórí ọmọ ogun lọ sin àwọn tó kú, ó sì wá ọ̀nà láti pa gbogbo ọkùnrin tó wà ní Édómù. 16 (Nítorí oṣù mẹ́fà ni Jóábù àti gbogbo Ísírẹ́lì fi gbé ibẹ̀ títí ó fi pa gbogbo ọkùnrin tó wà ní Édómù run.*) 17 Àmọ́ Hádádì fẹsẹ̀ fẹ pẹ̀lú àwọn kan lára ìránṣẹ́ bàbá rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Édómù, wọ́n sì lọ sí Íjíbítì; ọmọdé ni Hádádì nígbà yẹn. 18 Nítorí náà, wọ́n kúrò ní Mídíánì, wọ́n sì wá sí Páránì. Wọ́n kó àwọn ọkùnrin kan láti Páránì,+ wọ́n sì wá sí Íjíbítì, lọ́dọ̀ Fáráò ọba Íjíbítì, ẹni tó fún un ní ilé, tó ṣètò bí á ṣe máa rí oúnjẹ gbà, tó sì fún un ní ilẹ̀. 19 Hádádì rí ojú rere Fáráò débi pé ó fún un ní àbúrò ayaba Tápénésì, ìyàwó rẹ̀, pé kó fi ṣe aya. 20 Nígbà tó yá, àbúrò Tápénésì bí ọmọkùnrin kan fún un, Génúbátì lorúkọ rẹ̀, Tápénésì tọ́ ọ dàgbà* ní ilé Fáráò, Génúbátì sì ń gbé ní ilé Fáráò láàárín àwọn ọmọ Fáráò.

21 Hádádì gbọ́ ní Íjíbítì pé Dáfídì ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀+ àti pé Jóábù olórí ọmọ ogun ti kú.+ Torí náà, Hádádì sọ fún Fáráò pé: “Jẹ́ kí n lọ, kí n lè lọ sí ilẹ̀ mi.” 22 Àmọ́ Fáráò sọ fún un pé: “Kí lo fẹ́ tí o kò ní lọ́dọ̀ mi tí o fi fẹ́ lọ sí ilẹ̀ rẹ?” Ó fèsì pé: “Kò sí, àmọ́ jọ̀wọ́ jẹ́ kí n lọ.”

23 Ọlọ́run tún gbé alátakò míì dìde+ sí Sólómọ́nì, ìyẹn Résónì ọmọ Élíádà, ẹni tó sá kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀, Hadadésà+ ọba Sóbà. 24 Ó kó àwọn ọkùnrin jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí àwọn jàǹdùkú* nígbà tí Dáfídì ṣẹ́gun*+ àwọn ọkùnrin Sóbà. Nítorí náà, wọ́n lọ sí Damásíkù,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀, wọ́n sì ń ṣàkóso ní Damásíkù. 25 Ó di alátakò Ísírẹ́lì ní ìgbà ayé Sólómọ́nì, ó dá kún jàǹbá tí Hádádì ṣe, ó sì kórìíra Ísírẹ́lì gan-an nígbà tó ń jọba lórí Síríà.

26 Ẹnì kan wà tó ń jẹ́ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì nínú ẹ̀yà Éfúrémù, ó wá láti Sérédà, ìránṣẹ́ Sólómọ́nì+ ni. Sérúà lorúkọ ìyá rẹ̀, opó sì ni. Òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀* sí ọba.+ 27 Ohun tó jẹ́ kó ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni pé: Sólómọ́nì mọ Òkìtì,*+ ó sì dí àlàfo Ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀.+ 28 Ọkùnrin tó dáńgájíá ni Jèróbóámù. Nígbà tí Sólómọ́nì rí i pé ọ̀dọ́kùnrin náà jẹ́ òṣìṣẹ́ kára, ó fi í ṣe alábòójútó+ gbogbo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ọ̀ranyàn ní ilé Jósẹ́fù. 29 Ní àkókò yẹn, Jèróbóámù jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wòlíì Áhíjà+ ọmọ Ṣílò sì rí i lọ́nà. Ẹ̀wù tuntun ló wà lọ́rùn Áhíjà, àwọn méjèèjì nìkan ló sì wà ní pápá. 30 Áhíjà di ẹ̀wù tuntun tó wà lọ́rùn rẹ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá (12). 31 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Jèróbóámù pé:

“Gba mẹ́wàá yìí, torí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Wò ó, màá fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Sólómọ́nì, màá sì fún ọ ní ẹ̀yà mẹ́wàá.+ 32 Àmọ́ ẹ̀yà kan ṣì máa jẹ́ tirẹ̀+ nítorí ìránṣẹ́ mi Dáfídì+ àti nítorí Jerúsálẹ́mù, ìlú tí mo yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì.+ 33 Ohun tí màá ṣe nìyí torí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún Áṣítórétì, abo ọlọ́run àwọn ọmọ Sídónì, fún Kémóṣì, ọlọ́run Móábù àti fún Mílíkómù, ọlọ́run àwọn ọmọ Ámónì, wọn ò rìn ní àwọn ọ̀nà mi láti máa ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi àti láti máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìdájọ́ mi mọ́ bí Dáfídì bàbá Sólómọ́nì ti ṣe. 34 Àmọ́ mi ò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, màá ṣì fi ṣe olórí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi tí mo yàn,+ torí ó pa àwọn àṣẹ àti òfin mi mọ́. 35 Ṣùgbọ́n màá gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀, màá sì fi í fún ọ, ìyẹn ẹ̀yà mẹ́wàá.+ 36 Màá fún ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀yà kan ṣoṣo, kí Dáfídì ìránṣẹ́ mi lè máa ṣàkóso* níwájú mi nígbà gbogbo ní Jerúsálẹ́mù,+ ìlú tí mo yàn fún ara mi láti fi orúkọ mi sí. 37 Màá yàn ọ́, wàá ṣàkóso lórí gbogbo ohun tí o* fẹ́, wàá sì di ọba lórí Ísírẹ́lì. 38 Tí o bá ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ, tí o rìn ní àwọn ọ̀nà mi, tí o sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi láti máa pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́, bí Dáfídì ìránṣẹ́ mi ti ṣe,+ èmi náà á wà pẹ̀lú rẹ. Màá kọ́ ilé tó máa wà títí lọ fún ọ, bí mo ṣe kọ́ ọ fún Dáfídì,+ màá sì fún ọ ní Ísírẹ́lì. 39 Màá dójú ti àtọmọdọ́mọ Dáfídì nítorí èyí,+ àmọ́ kò ní jẹ́ títí lọ.’”+

40 Torí náà, Sólómọ́nì wá ọ̀nà láti pa Jèróbóámù, àmọ́ Jèróbóámù sá lọ sí Íjíbítì, lọ́dọ̀ Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì,+ ó sì ń gbé ní Íjíbítì títí Sólómọ́nì fi kú.

41 Ní ti ìyókù ìtàn Sólómọ́nì, gbogbo ohun tí ó ṣe àti ọgbọ́n rẹ̀, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn Sólómọ́nì?+ 42 Gbogbo ọdún* tí Sólómọ́nì fi jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ ogójì (40) ọdún. 43 Níkẹyìn, Sólómọ́nì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀; Rèhóbóámù+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

12 Rèhóbóámù lọ sí Ṣékémù, nítorí gbogbo Ísírẹ́lì ti wá sí Ṣékémù+ láti fi í jọba.+ 2 Gbàrà tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì gbọ́ (ó ṣì wà ní Íjíbítì torí ó sá lọ nítorí Ọba Sólómọ́nì, ó sì ń gbé ní Íjíbítì),+ 3 wọ́n ránṣẹ́ pè é. Lẹ́yìn náà, Jèróbóámù àti gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì wá bá Rèhóbóámù, wọ́n sì sọ pé: 4 “Bàbá rẹ mú kí àjàgà wa wúwo.+ Àmọ́ tí o bá mú kí iṣẹ́ tó nira tí bàbá rẹ fún wa rọ̀ wá lọ́rùn, tí o sì mú kí àjàgà tó wúwo* tó fi kọ́ wa lọ́rùn fúyẹ́, a ó máa sìn ọ́.”

5 Ló bá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa lọ, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta; kí ẹ pa dà wá.” Torí náà, àwọn èèyàn náà lọ.+ 6 Ọba Rèhóbóámù wá fọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbà ọkùnrin* tó bá Sólómọ́nì bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà tó wà láàyè, ó ní: “Ẹ gbà mí nímọ̀ràn, èsì wo ni ká fún àwọn èèyàn yìí?” 7 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Tí o bá sọ ara rẹ di ìránṣẹ́ àwọn èèyàn yìí lónìí, tí o ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, tí o sì fún wọn ní èsì rere, ìwọ ni wọ́n á máa sìn títí lọ.”

8 Àmọ́, ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbà ọkùnrin* fún un, ó sì fọ̀rọ̀ lọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà, àmọ́ tí wọ́n ti di ẹmẹ̀wà* rẹ̀ báyìí.+ 9 Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ẹ gbà mí nímọ̀ràn, èsì wo ni ká fún àwọn èèyàn tó sọ fún mi pé, ‘Mú kí àjàgà tí bàbá rẹ fi kọ́ wa lọ́rùn fúyẹ́’?” 10 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí o máa sọ fún àwọn èèyàn tó sọ fún ọ pé, ‘Bàbá rẹ mú kí àjàgà wa wúwo, ṣùgbọ́n mú kí ó fúyẹ́ lọ́rùn wa’; ohun tí wàá sọ fún wọn ni pé, ‘Ọmọ ìka ọwọ́ mi tó kéré jù* yóò nípọn ju ìbàdí bàbá mi lọ. 11 Bàbá mi fi àjàgà tó wúwo kọ́ yín lọ́rùn, àmọ́ ńṣe ni màá fi kún àjàgà yín. Pàṣán ni bàbá mi fi nà yín, ṣùgbọ́n kòbókò oníkókó ni màá fi nà yín.’”

12 Jèróbóámù àti gbogbo àwọn èèyàn náà wá bá Rèhóbóámù ní ọjọ́ kẹta, bí ọba ṣe sọ pé: “Ẹ pa dà wá bá mi ní ọjọ́ kẹta.”+ 13 Àmọ́, ńṣe ni ọba jágbe mọ́ àwọn èèyàn náà, kò gba ìmọ̀ràn tí àwọn àgbà ọkùnrin* fún un. 14 Ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin fún un ló tẹ̀ lé, ó sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Bàbá mi mú kí àjàgà yín wúwo, ṣùgbọ́n ṣe ni màá fi kún àjàgà yín. Pàṣán ni bàbá mi fi nà yín, ṣùgbọ́n kòbókò oníkókó ni màá fi nà yín.” 15 Nítorí náà, ọba ò fetí sí àwọn èèyàn náà, torí pé Jèhófà ló mú kí ìyípadà náà wáyé,+ kí ọ̀rọ̀ Jèhófà lè ṣẹ, èyí tó gbẹnu Áhíjà+ ọmọ Ṣílò sọ fún Jèróbóámù ọmọ Nébátì.

16 Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i pé ọba ò gbọ́ tiwọn, àwọn èèyàn náà fún ọba lésì pé: “Kí ló pa àwa àti Dáfídì pọ̀? A ò ní ogún kankan nínú ọmọ Jésè. Lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì. Máa mójú tó ilé ara rẹ, ìwọ Dáfídì!” Bí Ísírẹ́lì ṣe pa dà sí ilé* wọn nìyẹn.+ 17 Àmọ́ Rèhóbóámù ń jọba nìṣó lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé ní àwọn ìlú Júdà.+

18 Lẹ́yìn náà, Ọba Rèhóbóámù rán Ádórámù,+ ẹni tó jẹ́ olórí àwọn tí ọba ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa. Agbára káká ni Ọba Rèhóbóámù fi rọ́nà gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti sá lọ sí Jerúsálẹ́mù.+ 19 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń ṣọ̀tẹ̀+ sí ilé Dáfídì títí di òní yìí.

20 Gbàrà tí gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ pé Jèróbóámù ti pa dà dé, wọ́n pè é wá sí àpéjọ, wọ́n sì fi jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+ Kò sí ìkankan lára àwọn èèyàn náà tó wà lẹ́yìn ilé Dáfídì àfi ẹ̀yà Júdà.+

21 Nígbà tí Rèhóbóámù dé Jerúsálẹ́mù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló pe gbogbo ilé Júdà àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) akọgun,* láti bá ilé Ísírẹ́lì jà, kí wọ́n lè gba ipò ọba pa dà fún Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì.+ 22 Ìgbà náà ni Ọlọ́run tòótọ́ bá Ṣemáyà,+ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀, ó ní: 23 “Sọ fún Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì ọba Júdà àti gbogbo ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú ìyókù àwọn èèyàn náà pé, 24 ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ lọ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn arákùnrin yín jà. Kí kálukú yín pa dà sí ilé rẹ̀, torí èmi ló mú kí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀.”’”+ Nítorí náà, wọ́n ṣe ohun tí Jèhófà sọ, wọ́n sì pa dà sílé bí Jèhófà ṣe sọ fún wọn.

25 Jèróbóámù wá kọ́* Ṣékémù+ ní agbègbè olókè Éfúrémù, ó sì ń gbé ibẹ̀. Láti ibẹ̀, ó lọ kọ́* Pénúélì.+ 26 Jèróbóámù sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Ní báyìí, ìjọba náà máa pa dà sí ilé Dáfídì.+ 27 Torí bí àwọn èèyàn yìí bá ṣì ń lọ rú ẹbọ ní ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù,+ ọkàn wọn máa pa dà sọ́dọ̀ olúwa wọn, Rèhóbóámù ọba Júdà. Ó dájú pé wọ́n á pa mí, wọ́n á sì pa dà sọ́dọ̀ Rèhóbóámù ọba Júdà.” 28 Lẹ́yìn tí ọba gba ìmọ̀ràn, ó ṣe ère ọmọ màlúù wúrà méjì,+ ó sì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Wàhálà yìí ti pọ̀ jù fún yín láti máa lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ọlọ́run rẹ rèé, ìwọ Ísírẹ́lì, tí ó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+ 29 Ìgbà náà ni ó gbé ọ̀kan sí Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì gbé ìkejì sí Dánì.+ 30 Nǹkan yìí mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀,+ àwọn èèyàn náà sì lọ títí dé Dánì kí wọ́n lè jọ́sìn èyí tó wà níbẹ̀.

31 Ó kọ́ àwọn ilé ìjọsìn sórí àwọn ibi gíga, ó sì yan àwọn àlùfáà látinú gbogbo àwọn èèyàn náà, àwọn tí kì í ṣe ọmọ Léfì.+ 32 Jèróbóámù tún dá àjọyọ̀ kan sílẹ̀ ní oṣù kẹjọ, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù náà, bí àjọyọ̀ tó wà ní Júdà.+ Ó rú ẹbọ sí àwọn ère ọmọ màlúù tó ṣe sórí àwọn pẹpẹ tó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì yan àwọn àlùfáà ní Bẹ́tẹ́lì fún àwọn ibi gíga tó ṣe. 33 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ọrẹ wá sórí pẹpẹ tó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún ní oṣù kẹjọ, ní oṣù tí òun fúnra rẹ̀ yàn; ó dá àjọyọ̀ kan sílẹ̀ fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì, ó sì lọ sórí pẹpẹ láti mú ọrẹ àti ẹbọ rú èéfín.

13 Èèyàn Ọlọ́run+ kan wá láti Júdà sí Bẹ́tẹ́lì bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún un, nígbà tí Jèróbóámù dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ+ láti mú ẹbọ rú èéfín. 2 Ó kéde sórí pẹpẹ náà bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún un, ó ní: “Ìwọ pẹpẹ, pẹpẹ! Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Wò ó! Wọ́n á bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jòsáyà+ ní ilé Dáfídì! Ó máa fi àwọn àlùfáà ibi gíga rúbọ lórí rẹ, ìyẹn àwọn tó ń mú ẹbọ rú èéfín lórí rẹ, ó sì máa sun egungun èèyàn lórí rẹ.’”+ 3 Ó fi àmì kan* hàn ní ọjọ́ yẹn, ó sọ pé: “Àmì* tí Jèhófà sọ nìyí: Wò ó! Pẹpẹ náà yóò là sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, eérú* tó wà lórí rẹ̀ yóò sì dà nù.”

4 Bí Jèróbóámù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà kéde sórí pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì, ó na ọwọ́ rẹ̀ láti ibi pẹpẹ, ó sì sọ pé: “Ẹ gbá a mú!”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọwọ́ tó nà sí i gbẹ,* kò sì lè fà á pa dà.+ 5 Ni pẹpẹ náà bá là sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, eérú sì dà kúrò lórí pẹpẹ náà, bí àmì* tí Jèhófà sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà.

6 Ọba wá sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà pé: “Jọ̀wọ́, bá mi bẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ* pé kó ṣojú rere sí mi, sì bá mi gbàdúrà kí ọwọ́ mi lè pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.”+ Ni èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà bá bẹ Jèhófà pé kó ṣojú rere sí i, ọwọ́ ọba sì pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. 7 Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà pé: “Jẹ́ ká jọ lọ sílé, kí o lè jẹun, kí n sì fún ọ ní ẹ̀bùn.” 8 Àmọ́ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà sọ fún ọba pé: “Tí o bá tiẹ̀ fún mi ní ìdajì ilé rẹ, mi ò ní bá ọ lọ, kí n sì jẹun tàbí kí n mu omi ní ibí yìí. 9 Nítorí àṣẹ tí Jèhófà pa fún mi ni pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ jẹun tàbí kí o mu omi, o ò sì gbọ́dọ̀ gba ọ̀nà tí o gbà lọ pa dà.’” 10 Torí náà, ó gba ọ̀nà míì lọ, kò sì gba ọ̀nà tó gbà wá sí Bẹ́tẹ́lì pa dà.

11 Wòlíì àgbà kan wà tó ń gbé ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn ọmọ rẹ̀ wá sílé, wọ́n sì ròyìn gbogbo ohun tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe lọ́jọ́ náà ní Bẹ́tẹ́lì fún un àti ọ̀rọ̀ tó sọ fún ọba. Lẹ́yìn tí wọ́n sọ gbogbo rẹ̀ fún bàbá wọn, 12 bàbá wọn béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ọ̀nà wo ni ó gbà lọ?” Torí náà, àwọn ọmọ rẹ̀ fi ọ̀nà tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, tó wá láti Júdà, gbà lọ hàn án. 13 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi di ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”* Wọ́n bá a di ohun ti wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* ó sì gùn ún.

14 Ó wá èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà lọ, ó sì rí i tó jókòó lábẹ́ igi ńlá kan. Ni ó bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ìwọ ni èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tó wá láti Júdà?”+ Ó fèsì pé: “Èmi ni.” 15 Ó sọ fún un pé: “Jẹ́ ká jọ lọ sílé, kí o lè jẹun.” 16 Àmọ́ ó sọ pé: “Mi ò lè bá ọ pa dà tàbí kí n ṣe ohun tí o sọ, bẹ́ẹ̀ ni mi ò ní jẹun tàbí kí n mu omi pẹ̀lú rẹ ní ibí yìí. 17 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ fún mi ni pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ jẹun tàbí kí o mu omi níbẹ̀. O ò sì gbọ́dọ̀ gba ọ̀nà tí o gbà lọ pa dà.’” 18 Ni ó bá sọ fún un pé: “Wòlíì bíi tìẹ ni èmi náà, áńgẹ́lì kan sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún mi pé, ‘Ní kó bá ọ pa dà sílé, kí ó lè jẹun, kí ó sì mu omi.’” (Ó tàn án jẹ.) 19 Nítorí náà, ó bá a pa dà lọ kí ó lè jẹun, kí ó sì mu omi.

20 Bí wọ́n ti jókòó nídìí tábìlì, Jèhófà bá wòlíì tí ó mú un pa dà wá sọ̀rọ̀, 21 ó pe èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tí ó wá láti Júdà, ó sì sọ pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Nítorí pé o kọ ìtọ́ni Jèhófà, o kò sì pa àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, 22 ṣùgbọ́n o pa dà lọ, kí o lè jẹun, kí o sì mu omi ní ibi tí ó sọ fún ọ pé, “Má jẹun, má sì mu omi,” wọn ò ní sin òkú rẹ sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba ńlá rẹ+ sí.’”

23 Lẹ́yìn tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà jẹun tán, tí ó sì mu, wòlíì àgbà náà de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* fún wòlíì tí ó mú pa dà wá. 24 Lẹ́yìn náà, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà bọ́ sọ́nà, àmọ́ kìnnìún kan yọ sí i lójú ọ̀nà, ó sì pa á.+ Òkú rẹ̀ wà lójú ọ̀nà, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó gùn sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; kìnnìún náà sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà. 25 Àwọn èèyàn tó ń kọjá rí òkú náà lójú ọ̀nà àti kìnnìún tó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà. Wọ́n wọ inú ìlú tí wòlíì àgbà náà ń gbé, wọ́n sì ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

26 Nígbà tí wòlíì tí ó mú un pa dà láti ojú ọ̀nà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tó kọ ìtọ́ni Jèhófà ni;+ ìdí nìyẹn tí Jèhófà ṣe fi í lé kìnnìún lọ́wọ́ láti ṣe é léṣe, kí ó sì pa á, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún un.”+ 27 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”* Torí náà, wọ́n bá a dè é mọ́ ọn. 28 Lẹ́yìn náà, ó bọ́ sọ́nà, ó sì rí òkú náà lójú ọ̀nà pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kìnnìún náà kò jẹ òkú náà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà léṣe. 29 Wòlíì náà gbé òkú èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e pa dà wá sí ìlú rẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, kí ó sì sin ín. 30 Torí náà, ó sin òkú náà sínú ibojì ti ara rẹ̀, wọ́n sì ń sunkún nítorí rẹ̀, wọ́n ń sọ pé: “Ó mà ṣe o, arákùnrin mi!” 31 Lẹ́yìn tí ó sin ín, ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Nígbà tí mo bá kú, ibi tí mo sin èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ yìí sí ni kí ẹ sin mí sí. Ẹ̀gbẹ́ egungun rẹ̀+ ni kí ẹ kó egungun mi sí. 32 Ó dájú pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tí wòlíì náà kéde sórí pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì àti sórí gbogbo àwọn ilé ìjọsìn tó wà lórí àwọn ibi gíga+ ní àwọn ìlú Samáríà máa ṣẹ.”+

33 Kódà lẹ́yìn tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, Jèróbóámù kò yí pa dà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀, ńṣe ló ń yan ẹnikẹ́ni lára àwọn èèyàn náà láti fi ṣe àlùfáà ní àwọn ibi gíga.+ Ẹni tí ó bá wù ú ló máa ń fi ṣe àlùfáà,* á sì sọ pé: “Jẹ́ kó di ọ̀kan lára àwọn àlùfáà ibi gíga.”+ 34 Ẹ̀ṣẹ̀ agbo ilé Jèróbóámù+ yìí ló yọrí sí ìparun wọn, tí wọ́n sì pa rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀.+

14 Ní àkókò yẹn, Ábíjà ọmọkùnrin Jèróbóámù ń ṣàìsàn. 2 Torí náà, Jèróbóámù sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, dìde, yí ìmúra rẹ pa dà kí wọ́n má bàa mọ̀ pé ìyàwó Jèróbóámù ni ọ́, kí o sì lọ sí Ṣílò. Wò ó! Wòlíì Áhíjà wà níbẹ̀. Òun ni ó sọ nípa mi pé màá di ọba lórí àwọn èèyàn yìí.+ 3 Mú búrẹ́dì mẹ́wàá dání àti kéèkì tí a bu nǹkan wọ́n àti ṣágo* oyin, kí o sì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó máa sọ ohun tí á ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà fún ọ.”

4 Ìyàwó Jèróbóámù ṣe ohun tí ọkọ rẹ̀ sọ. Ó dìde, ó lọ sí Ṣílò,+ ó sì wá sí ilé Áhíjà. Ojú Áhíjà là sílẹ̀, àmọ́ kò ríran mọ́ nítorí ọjọ́ orí rẹ̀.

5 Àmọ́ Jèhófà ti sọ fún Áhíjà pé: “Wò ó, ìyàwó Jèróbóámù ń bọ̀ wá wádìí nípa ọmọ rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ, torí pé ọmọ náà ń ṣàìsàn. Màá sọ fún ọ, ohun tí o máa sọ fún un.* Tí ó bá dé, kò ní jẹ́ kí o dá òun mọ̀.”

6 Bí Áhíjà ṣe gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó ń bọ̀ lẹ́nu ọ̀nà, ó sọ pé: “Wọlé, ìyàwó Jèróbóámù. Kí ló dé tí o fi ṣe bíi pé ẹlòmíràn ni ọ́? Iṣẹ́ tó lágbára kan wà tí Ọlọ́run ní kí n jẹ́ fún ọ. 7 Lọ sọ fún Jèróbóámù pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Mo gbé ọ dìde láti àárín àwọn èèyàn rẹ, kí n lè sọ ọ́ di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+ 8 Lẹ́yìn náà, mo fa ìjọba ya kúrò ní ilé Dáfídì, mo sì fún ọ.+ Àmọ́, o kò ṣe bí ìránṣẹ́ mi Dáfídì, ẹni tí ó pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ó sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé mi, tí ó ṣe kìkì ohun tí ó tọ́ lójú mi.+ 9 Ohun tí o ṣe burú ju ti gbogbo àwọn tó ṣáájú rẹ, o ṣe ọlọ́run míì fún ara rẹ àti àwọn ère onírin* láti mú mi bínú,+ o sì kẹ̀yìn sí mi.+ 10 Nítorí ohun tí o ṣe yìí, màá mú àjálù bá ilé Jèróbóámù, màá pa gbogbo ọkùnrin* ilé Jèróbóámù rẹ́,* títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì, màá sì gbá ilé Jèróbóámù+ dà nù, bí ìgbà tí èèyàn gbá ìgbẹ́ ẹran kúrò láìku nǹkan kan! 11 Èèyàn Jèróbóámù èyíkéyìí tí ó bá kú sí ìlú ni ajá yóò jẹ; èyí tí ó bá sì kú sí pápá ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ, nítorí Jèhófà ti sọ ọ́.”’

12 “Ní báyìí, gbéra; máa lọ sí ilé rẹ. Bí o bá ṣe wọ ìlú náà, ọmọ náà máa kú. 13 Gbogbo Ísírẹ́lì á ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n á sì sin ín, torí òun nìkan ni wọ́n máa sin sínú sàréè lára àwọn ará ilé Jèróbóámù, nítorí pé òun nìkan ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì rí ohun rere nínú rẹ̀ ní ilé Jèróbóámù. 14 Jèhófà yóò gbé ọba kan dìde fún ara rẹ̀ lórí Ísírẹ́lì, tí ó máa mú* ilé Jèróbóámù+ kúrò láti ọjọ́ náà lọ, kódà ó lè jẹ́ nísinsìnyí. 15 Jèhófà yóò kọ lu Ísírẹ́lì, á sì dà bí esùsú* tó ń mì lòólòó lójú omi, yóò fa Ísírẹ́lì tu kúrò lórí ilẹ̀ dáradára yìí tó fún àwọn baba ńlá wọn,+ yóò sì tú wọn ká kọjá Odò,*+ nítorí wọ́n ṣe àwọn òpó òrìṣà,*+ tí wọ́n sì ń mú Jèhófà bínú. 16 Yóò pa Ísírẹ́lì tì nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù dá àti èyí tó mú kí Ísírẹ́lì dá.”+

17 Ni ìyàwó Jèróbóámù bá dìde, ó bọ́ sọ́nà, ó sì dé Tírísà. Bí ó ṣe ń dé ibi àbáwọlé, ọmọ náà kú. 18 Torí náà, wọ́n sin ín, gbogbo Ísírẹ́lì sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gba ẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì Áhíjà sọ.

19 Ní ti ìyókù ìtàn Jèróbóámù, bí ó ṣe jagun+ àti bí ó ṣe ṣàkóso, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì. 20 Gbogbo ọdún* tí Jèróbóámù fi jọba jẹ́ ọdún méjìlélógún (22), lẹ́yìn náà, ó sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ Nádábù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+

21 Ní àkókò yẹn, Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì ti di ọba ní Júdà. Ẹni ọdún mọ́kànlélógójì (41) ni Rèhóbóámù nígbà tó di ọba, ó sì fi ọdún mẹ́tàdínlógún (17) jọba ní Jerúsálẹ́mù, ìlú tí Jèhófà yàn+ nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ sí.+ Orúkọ ìyá Rèhóbóámù ni Náámà, ọmọ Ámónì+ sì ni. 22 Júdà ń ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ wọ́n fi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá mú un bínú ju bí àwọn baba ńlá wọn ṣe mú un bínú lọ.+ 23 Àwọn náà ń kọ́ ibi gíga àti àwọn ọwọ̀n òrìṣà pẹ̀lú àwọn òpó òrìṣà*+ fún ara wọn sórí gbogbo òkè+ àti sábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+ 24 Àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin tó wà ní tẹ́ńpìlì tún wà ní ilẹ̀ náà.+ Ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ni àwọn náà ń ṣe.

25 Ní ọdún karùn-ún Ọba Rèhóbóámù, Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ 26 Ó kó àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé* ọba.+ Gbogbo nǹkan pátá ló kó, títí kan gbogbo apata wúrà tí Sólómọ́nì ṣe.+ 27 Nítorí náà, Ọba Rèhóbóámù ṣe àwọn apata bàbà láti fi rọ́pò wọn, ó sì fi wọ́n sí ìkáwọ́ àwọn olórí ẹ̀ṣọ́* tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba. 28 Nígbàkigbà tí ọba bá wá sí ilé Jèhófà, àwọn ẹ̀ṣọ́ á gbé àwọn apata náà, lẹ́yìn náà, wọ́n á dá wọn pa dà sí yàrá ẹ̀ṣọ́.

29 Ní ti ìyókù ìtàn Rèhóbóámù, gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà?+ 30 Ìgbà gbogbo ni ogun ń wáyé láàárín Rèhóbóámù àti Jèróbóámù.+ 31 Níkẹyìn, Rèhóbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Náámà, ọmọ Ámónì+ sì ni. Ábíjámù*+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

15 Ní ọdún kejìdínlógún Ọba Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì, Ábíjámù di ọba lórí Júdà.+ 2 Ọdún mẹ́ta ló fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Máákà,+ ọmọ ọmọ Ábíṣálómù. 3 Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí bàbá rẹ̀ dá ṣáájú rẹ̀ ni òun náà dá, kò sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bíi Dáfídì baba ńlá rẹ̀. 4 Àmọ́, nítorí Dáfídì,+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ jẹ́ kí àtọmọdọ́mọ rẹ̀ máa ṣàkóso* ní Jerúsálẹ́mù,+ ó gbé ọmọ rẹ̀ dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó sì jẹ́ kí Jerúsálẹ́mù máa wà nìṣó. 5 Dáfídì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kò kúrò nínú gbogbo ohun tí Ó pa láṣẹ fún un, àfi nínú ọ̀ràn Ùráyà ọmọ Hétì.+ 6 Ogun sì ń wáyé láàárín Rèhóbóámù àti Jèróbóámù ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.+

7 Ní ti ìyókù ìtàn Ábíjámù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà?+ Bákan náà, ogun wáyé láàárín Ábíjámù àti Jèróbóámù.+ 8 Níkẹyìn, Ábíjámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì; Ásà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+

9 Ní ogún ọdún Jèróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Ásà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí Júdà. 10 Ọdún mọ́kànlélógójì (41) ni ó fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ àgbà ni Máákà+ ọmọ ọmọ Ábíṣálómù. 11 Ásà ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ bíi Dáfídì baba ńlá rẹ̀. 12 Ó lé àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin tó wà ní tẹ́ńpìlì kúrò ní ilẹ̀ náà,+ ó sì mú gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin* tí àwọn baba ńlá rẹ̀ ṣe kúrò.+ 13 Ó tiẹ̀ tún yọ Máákà+ ìyá rẹ̀ àgbà kúrò ní ipò ìyá ọba,* torí pé ó ṣe òrìṣà ẹ̀gbin tí wọ́n fi ń jọ́sìn òpó òrìṣà.* Ásà gé òrìṣà ẹ̀gbin+ rẹ̀ lulẹ̀, ó sì sun ún ní Àfonífojì Kídírónì.+ 14 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò.+ Síbẹ̀, Ásà fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé* rẹ̀. 15 Ó kó àwọn ohun tí òun àti bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá sínú ilé Jèhófà, ìyẹn fàdákà, wúrà àti àwọn ohun èlò míì.+

16 Ìgbà gbogbo ni ogun ń wáyé láàárín Ásà àti Bááṣà+ ọba Ísírẹ́lì. 17 Torí náà, Bááṣà ọba Ísírẹ́lì wá dojú kọ Júdà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́* Rámà,+ kí ẹnikẹ́ni má bàa jáde tàbí kí ó wọlé sọ́dọ̀* Ásà ọba Júdà.+ 18 Ni Ásà bá kó gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ibi ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba, ó sì kó wọn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ọba Ásà wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí Bẹni-hádádì ọmọ Tábúrímónì ọmọ Hésíónì, ọba Síríà,+ tó ń gbé ní Damásíkù, ó sọ pé: 19 “Àdéhùn* kan wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín bàbá mi àti bàbá rẹ. Mo fi ẹ̀bùn fàdákà àti wúrà ránṣẹ́ sí ọ. Wò ó, lọ yẹ àdéhùn* tí o bá Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ṣe, kó lè pa dà lẹ́yìn mi.” 20 Bẹni-hádádì ṣe ohun tí Ọba Ásà sọ, ó rán àwọn olórí ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko àwọn ìlú Ísírẹ́lì, wọ́n sì ṣá Íjónì,+ Dánì+ àti Ebẹli-bẹti-máákà balẹ̀ pẹ̀lú gbogbo Kínérétì àti gbogbo ilẹ̀ Náfútálì. 21 Nígbà tí Bááṣà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló jáwọ́ nínú kíkọ́* Rámà, ó sì ń gbé ní Tírísà.+ 22 Ọba Ásà wá pe gbogbo Júdà, láìyọ ẹnì kankan sílẹ̀, wọ́n kó àwọn òkúta àti ẹ̀là gẹdú tó wà ní Rámà, tí Bááṣà fi ń kọ́lé, Ọba Ásà sì fi wọ́n kọ́* Gébà+ ní Bẹ́ńjámínì àti Mísípà.+

23 Ní ti gbogbo ìyókù ìtàn Ásà àti gbogbo agbára rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti àwọn ìlú tí ó kọ́,* ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? Àmọ́, nígbà tí ó darúgbó, àìsàn kan mú un ní ẹsẹ̀.+ 24 Níkẹyìn, Ásà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú wọn ní Ìlú Dáfídì baba ńlá rẹ̀; Jèhóṣáfátì+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

25 Nádábù+ ọmọ Jèróbóámù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún kejì Ásà ọba Júdà, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì. 26 Ohun búburú ló ń ṣe ní ojú Jèhófà, ó sì ń rìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀+ àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí bàbá rẹ̀ mú kí Ísírẹ́lì dá.+ 27 Bááṣà ọmọ Áhíjà ará ilé Ísákà dìtẹ̀ mọ́ ọn, Bááṣà sì pa á ní Gíbétónì+ tó jẹ́ ti àwọn Filísínì, nígbà tí Nádábù àti gbogbo Ísírẹ́lì dó ti Gíbétónì. 28 Bí Bááṣà ṣe pa á nìyẹn ní ọdún kẹta Ásà ọba Júdà, ó sì jọba ní ipò rẹ̀. 29 Gbàrà tí ó di ọba, ó ṣá gbogbo ilé Jèróbóámù balẹ̀. Kò ṣẹ́ alààyè kankan kù lára àwọn ará ilé Jèróbóámù; ó ní kí wọ́n pa wọ́n rẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Áhíjà ọmọ Ṣílò,+ sọ. 30 Èyí jẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù dá, tí ó sì mú kí Ísírẹ́lì náà dá àti nítorí pé ó mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú gan-an. 31 Ní ti ìyókù ìtàn Nádábù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 32 Ìgbà gbogbo ni ogun ń wáyé láàárín Ásà àti Bááṣà ọba Ísírẹ́lì.+

33 Ní ọdún kẹta Ásà ọba Júdà, Bááṣà ọmọ Áhíjà di ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní Tírísà, ó sì fi ọdún mẹ́rìnlélógún (24) ṣàkóso.+ 34 Àmọ́ ohun búburú ló ń ṣe ní ojú Jèhófà,+ ó sì rìn ní ọ̀nà Jèróbóámù àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó mú kí Ísírẹ́lì dá.+

16 Jèhófà gbẹnu Jéhù+ ọmọ Hánáánì+ kéde ìdájọ́ sórí Bááṣà pé: 2 “Mo gbé ọ dìde láti inú iyẹ̀pẹ̀, mo sì sọ ọ́ di aṣáájú lórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì,+ ṣùgbọ́n ò ń rìn ní ọ̀nà Jèróbóámù, o sì mú kí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì ṣẹ̀, tí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá+ sì mú mi bínú. 3 Torí náà, màá gbá Bááṣà àti ilé rẹ̀ dà nù bí ẹni gbálẹ̀, màá sì ṣe ilé rẹ̀ bí ilé Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì. 4 Ajá ni yóò jẹ ará ilé Bááṣà èyíkéyìí tí ó bá kú sínú ìlú; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ni yóò sì jẹ ará ilé rẹ̀ èyíkéyìí tí ó bá kú sí pápá.”

5 Ní ti ìyókù ìtàn Bááṣà àti ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 6 Níkẹyìn, Bááṣà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sin ín sí Tírísà,+ Élà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀. 7 Jèhófà tún gbẹnu wòlíì Jéhù ọmọ Hánáánì kéde ìdájọ́ sórí Bááṣà àti ilé rẹ̀, nítorí gbogbo ìwà búburú tí ó hù ní ojú Jèhófà, tí ó fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mú un bínú, bí ilé Jèróbóámù àti nítorí pé ó ṣá a* balẹ̀.+

8 Ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, Élà ọmọ Bááṣà di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Tírísà, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso. 9 Ìránṣẹ́ rẹ̀ Símírì, tó jẹ́ olórí ìdajì àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ogun, dìtẹ̀ mọ́ ọn nígbà tó wà ní Tírísà, tí ó ń fi ọtí rọ ara rẹ̀ yó ní ilé Árísà, ẹni tí ó ń bójú tó agbo ilé ní Tírísà. 10 Símírì wọlé, ó ṣá a balẹ̀,+ ó sì pa á ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, ó sì jọba ní ipò rẹ̀. 11 Nígbà tí ó jọba, gbàrà tí ó gorí ìtẹ́, ó pa gbogbo ará ilé Bááṣà. Kò fi ọkùnrin* kankan sílẹ̀, ì báà jẹ́ ìbátan* rẹ̀ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ̀. 12 Bí Símírì ṣe pa gbogbo ilé Bááṣà rẹ́ nìyẹn, bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu wòlíì Jéhù kéde sórí Bááṣà.+ 13 Èyí jẹ́ nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Bááṣà àti Élà ọmọ rẹ̀ dá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n mú kí Ísírẹ́lì dá, tí wọ́n fi àwọn òrìṣà asán+ wọn mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú. 14 Ní ti ìyókù ìtàn Élà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì?

15 Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, Símírì di ọba ní Tírísà, ọjọ́ méje ló sì fi jọba nígbà tí àwọn ọmọ ogun dó ti Gíbétónì,+ tó jẹ́ ti àwọn Filísínì. 16 Nígbà tó yá, àwọn ọmọ ogun tó wà ní ibùdó gbọ́ tí wọ́n ń sọ pé: “Símírì ti dìtẹ̀, ó sì ti pa ọba.” Torí náà, gbogbo Ísírẹ́lì fi Ómírì,+ olórí àwọn ọmọ ogun jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì lọ́jọ́ yẹn ní ibùdó. 17 Ómírì àti gbogbo Ísírẹ́lì tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá gbéra ní Gíbétónì, wọ́n sì lọ dó ti Tírísà. 18 Nígbà tí Símírì rí i pé wọ́n ti gba ìlú náà, ó wọ inú ilé gogoro tó láàbò tó wà ní ilé* ọba, ó dáná sun ilé náà mọ́ ara rẹ̀ lórí, ó sì kú.+ 19 Èyí jẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ó ṣe ohun tí ó burú lójú Jèhófà, tí ó sì rìn ní ọ̀nà Jèróbóámù àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó mú kí Ísírẹ́lì dá.+ 20 Ní ti ìyókù ìtàn Símírì àti ọ̀tẹ̀ tí ó dì, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì?

21 Ìgbà náà ni àwọn èèyàn Ísírẹ́lì pín sí apá méjì. Apá kan lára wọn tẹ̀ lé Tíbínì ọmọ Gínátì, wọ́n fẹ́ fi jọba, apá kejì sì tẹ̀ lé Ómírì. 22 Àmọ́, àwọn èèyàn tó tẹ̀ lé Ómírì borí àwọn tó tẹ̀ lé Tíbínì ọmọ Gínátì. Torí náà, Tíbínì kú, Ómírì sì di ọba.

23 Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, Ómírì di ọba lórí Ísírẹ́lì, ọdún méjìlá (12) ló sì fi ṣàkóso. Ọdún mẹ́fà ló fi jọba ní Tírísà. 24 Ó ra òkè Samáríà lọ́wọ́ Ṣémérì ní tálẹ́ńtì* méjì fàdákà, ó kọ́ ìlú kan sórí òkè náà. Ó fi orúkọ Ṣémérì, ẹni tí ó ni* òkè náà pe ìlú tí ó kọ́, ó pè é ní Samáríà.*+ 25 Ómírì ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà nígbà gbogbo, tiẹ̀ tún burú ju ti gbogbo àwọn tó ṣáájú rẹ̀.+ 26 Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà Jèróbóámù ọmọ Nébátì àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó mú kí Ísírẹ́lì dá, tí wọ́n ń fi àwọn òrìṣà asán+ wọn mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú. 27 Ní ti ìyókù ìtàn Ómírì àti ohun tí ó ṣe àti àwọn ohun ribiribi tí ó gbé ṣe, ǹjẹ́ wọn kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 28 Níkẹyìn, Ómírì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Samáríà; Áhábù+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

29 Áhábù ọmọ Ómírì di ọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún kejìdínlógójì Ásà ọba Júdà, ọdún méjìlélógún (22) ni Áhábù ọmọ Ómírì sì fi ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà.+ 30 Ìwà Áhábù ọmọ Ómírì tún wá burú lójú Jèhófà ju ti gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀.+ 31 Àfi bíi pé nǹkan kékeré ni lójú rẹ̀ bó ṣe ń rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì, ó tún fẹ́ Jésíbẹ́lì+ ọmọ Etibáálì, ọba àwọn ọmọ Sídónì,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Báálì,+ ó sì ń forí balẹ̀ fún un. 32 Yàtọ̀ síyẹn, ó mọ pẹpẹ kan fún Báálì ní ilé* Báálì+ tí ó kọ́ sí Samáríà. 33 Áhábù tún ṣe òpó òrìṣà.*+ Áhábù sì ṣe ohun tó bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì nínú ju gbogbo àwọn ọba Ísírẹ́lì tó jẹ ṣáájú rẹ̀ lọ.

34 Nígbà tí Áhábù ń jọba, Híélì ará Bẹ́tẹ́lì tún Jẹ́ríkò kọ́. Ẹ̀mí Ábírámù àkọ́bí rẹ̀ ló fi dí i nígbà tó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀, ẹ̀mí Ségúbù àbíkẹ́yìn rẹ̀ ló sì fi dí i nígbà tó gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nàró, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jóṣúà ọmọ Núnì sọ.+

17 Nígbà náà, Èlíjà*+ ará Tíṣíbè, tó ń gbé ní Gílíádì+ sọ fún Áhábù pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí mò ń sìn* ti wà láàyè, kò ní sí òjò tàbí ìrì ní àwọn ọdún tó ń bọ̀, àfi nípa ọ̀rọ̀ mi!”+

2 Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó ní: 3 “Kúrò ní ibí yìí, kí o forí lé ìlà oòrùn, kí o sì fara pa mọ́ sí Àfonífojì Kérítì, tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì. 4 Kí o máa mu omi láti inú odò tó wà níbẹ̀, màá sì pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò pé kí wọ́n máa gbé oúnjẹ wá fún ọ níbẹ̀.”+ 5 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó lọ, ó sì ṣe ohun tí Jèhófà sọ; ó lọ sí Àfonífojì Kérítì tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, ó sì dúró síbẹ̀. 6 Àwọn ẹyẹ ìwò ń gbé búrẹ́dì àti ẹran wá fún un ní àárọ̀, wọ́n tún ń gbé búrẹ́dì àti ẹran wá fún un ní ìrọ̀lẹ́, ó sì ń mu omi láti inú odò náà.+ 7 Àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, odò náà gbẹ+ torí pé òjò ò rọ̀ ní ilẹ̀ náà.

8 Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó ní: 9 “Dìde, lọ sí Sáréfátì, ti Sídónì, kí o sì máa gbé ibẹ̀. Wò ó! Màá pàṣẹ fún opó kan níbẹ̀, pé kí ó máa gbé oúnjẹ wá fún ọ.”+ 10 Torí náà, ó dìde, ó sì lọ sí Sáréfátì. Nígbà tó dé ẹnu ọ̀nà ìlú náà, opó kan wà níbẹ̀ tó ń ṣa igi jọ. Torí náà, ó pè é, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, bá mi fi ife bu omi díẹ̀ wá kí n mu.”+ 11 Bí ó ṣe ń lọ bù ú wá, ó pè é, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, bá mi mú búrẹ́dì díẹ̀ bọ̀.” 12 Obìnrin náà wá sọ pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà láàyè, mi ò ní búrẹ́dì kankan, àfi ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú ìṣà kékeré.+ Ńṣe ni mò ń ṣa igi díẹ̀ jọ, kí n lè wọlé lọ ṣe nǹkan díẹ̀ fún èmi àti ọmọ mi. Lẹ́yìn tí a bá ti jẹ ẹ́ tán, a ò ní nǹkan míì, ikú ló kàn.”

13 Ni Èlíjà bá sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù. Wọlé lọ, kí o sì ṣe bí o ṣe sọ. Àmọ́ kọ́kọ́ bá mi fi ohun tó wà nílẹ̀ ṣe búrẹ́dì ribiti kékeré kan, kí o sì gbé e wá fún mi. Lẹ́yìn náà, o lè wá ṣe nǹkan kan fún ìwọ àti ọmọ rẹ. 14 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Ìyẹ̀fun kò ní tán nínú ìkòkò náà, òróró ò sì ní gbẹ nínú ìṣà kékeré náà títí di ọjọ́ tí Jèhófà yóò rọ òjò sórí ilẹ̀.’”+ 15 Nítorí náà, ó lọ, ó sì ṣe ohun tí Èlíjà sọ, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni obìnrin náà àti agbo ilé rẹ̀ pẹ̀lú Èlíjà fi rí oúnjẹ jẹ.+ 16 Ìyẹ̀fun kò tán nínú ìkòkò náà, òróró kò sì gbẹ nínú ìṣà kékeré náà, bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Èlíjà sọ.

17 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣàìsàn, àìsàn tó ṣe é sì le débi pé kò lè mí mọ́.+ 18 Ni ó bá sọ fún Èlíjà pé: “Kí ni mo ṣe fún ọ,* ìwọ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́? Ṣé o wá rán mi létí ẹ̀ṣẹ̀ tí mo dá, kí o sì pa mí lọ́mọ ni?”+ 19 Àmọ́, ó sọ fún un pé: “Gbé ọmọ rẹ fún mi.” Nígbà náà, ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀, ó gbé e lọ sí yàrá orí òrùlé, níbi tó ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn rẹ̀.+ 20 Ó ké pe Jèhófà pé: “Jèhófà Ọlọ́run mi,+ ṣé wàá tún mú àjálù bá opó tí mò ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni, tí o fi jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ kú?” 21 Lẹ́yìn náà, ó nà sórí ọmọ náà ní ìgbà mẹ́ta, ó sì ké pe Jèhófà pé: “Jèhófà Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, mú kí ẹ̀mí* ọmọ yìí sọ jí.” 22 Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Èlíjà,+ ẹ̀mí* ọmọ náà sọ jí, ó sì yè.+ 23 Èlíjà gbé ọmọ náà, ó gbé e sọ̀ kalẹ̀ láti yàrá orí òrùlé wá sínú ilé, ó sì gbé e fún ìyá rẹ̀; Èlíjà wá sọ pé: “Wò ó, ọmọ rẹ yè.”+ 24 Obìnrin náà wá sọ fún Èlíjà pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé èèyàn Ọlọ́run+ ni ọ́ lóòótọ́ àti pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà lẹ́nu rẹ jẹ́ òótọ́.”

18 Nígbà tó yá, Jèhófà bá Èlíjà sọ̀rọ̀ ní ọdún kẹta+ pé: “Lọ fara han Áhábù, màá sì rọ òjò sórí ilẹ̀.”+ 2 Torí náà, Èlíjà lọ rí Áhábù, nígbà tí ìyàn ṣì mú gidigidi+ ní Samáríà.

3 Láàárín àkókò náà, Áhábù pe Ọbadáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé. (Ọbadáyà bẹ̀rù Jèhófà gidigidi, 4 nígbà tí Jésíbẹ́lì+ ń pa àwọn wòlíì Jèhófà,* Ọbadáyà kó ọgọ́rùn-ún [100] wòlíì, ó fi wọ́n pa mọ́ ní àádọ́ta-àádọ́ta sínú ihò, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ àti omi.) 5 Áhábù wá sọ fún Ọbadáyà pé: “Lọ káàkiri ilẹ̀ yìí, sí gbogbo ìsun omi àti gbogbo àfonífojì. Bóyá a lè rí koríko tútù, tí a máa fún àwọn ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* wa, kí gbogbo àwọn ẹran wa má bàa kú.” 6 Nítorí náà, wọ́n pín ilẹ̀ tí wọ́n máa lọ láàárín ara wọn. Áhábù gba ọ̀nà kan lọ, Ọbadáyà sì gba ọ̀nà míì lọ.

7 Bí Ọbadáyà ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, Èlíjà wá pàdé rẹ̀. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ó dá a mọ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì sọ pé: “Ṣé ìwọ rèé, olúwa mi Èlíjà?”+ 8 Ó dá a lóhùn pé: “Èmi ni. Lọ sọ fún olúwa rẹ pé: ‘Èlíjà ti dé.’” 9 Àmọ́ Ọbadáyà sọ pé: “Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi tí o fi fẹ́ fa ìránṣẹ́ rẹ lé ọwọ́ Áhábù láti pa mí? 10 Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà láàyè, kò sí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba tí olúwa mi kò tíì ránṣẹ́ sí pé kí wọ́n wá ọ. Lẹ́yìn tí wọ́n bá sọ pé, ‘Kò sí níbí,’ ńṣe ló máa ní kí ìjọba náà tàbí orílẹ̀-èdè náà búra pé wọn kò rí ọ.+ 11 Ìwọ wá ń sọ pé, ‘Lọ sọ fún olúwa rẹ pé: “Èlíjà ti dé.”’ 12 Nígbà tí mo bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ẹ̀mí Jèhófà yóò gbé ọ lọ+ sí ibi tí mi ò mọ̀, tí mo bá wá sọ fún Áhábù, tí kò sì rí ọ, ó dájú pé yóò pa mí. Bẹ́ẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ ti ń bẹ̀rù Jèhófà láti ìgbà èwe rẹ̀ wá. 13 Ṣé wọn ò tíì sọ ohun tí mo ṣe fún olúwa mi nígbà tí Jésíbẹ́lì ń pa àwọn wòlíì Jèhófà ni, bí mo ṣe kó ọgọ́rùn-ún (100) lára àwọn wòlíì Jèhófà pa mọ́, ní àádọ́ta-àádọ́ta sínú ihò, tí mo sì ń fún wọn ní oúnjẹ àti omi?+ 14 Ní báyìí, o wá ń sọ pé, ‘Lọ sọ fún olúwa rẹ pé: “Èlíjà ti dé.”’ Ó dájú pé yóò pa mí.” 15 Àmọ́, Èlíjà sọ pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tí mò ń sìn* ti wà láàyè, òní ni màá fi ara mi han ọba.”

16 Torí náà, Ọbadáyà lọ pàdé Áhábù, ó sì sọ fún un, Áhábù sì wá pàdé Èlíjà.

17 Bí Áhábù ṣe rí Èlíjà báyìí, ó sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ rèé, ìwọ tí o kó wàhálà ńlá* bá Ísírẹ́lì?”

18 Ó fèsì pé: “Èmi kọ́ ló kó wàhálà bá Ísírẹ́lì, ìwọ àti ilé bàbá rẹ ni, ẹ pa àwọn àṣẹ Jèhófà tì, ẹ sì ń tẹ̀ lé àwọn Báálì.+ 19 Ní báyìí, pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ mi lórí Òkè Kámẹ́lì+ àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (450) wòlíì Báálì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) wòlíì òpó òrìṣà,*+ tó ń jẹun lórí tábìlì Jésíbẹ́lì.” 20 Torí náà, Áhábù ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì, ó sì kó àwọn wòlíì náà jọ sórí Òkè Kámẹ́lì.

21 Lẹ́yìn náà Èlíjà wá bá gbogbo àwọn èèyàn náà, ó sì sọ pé: “Ìgbà wo lẹ máa ṣiyèméjì* dà?+ Tó bá jẹ́ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ tẹ̀ lé e;+ àmọ́ tó bá jẹ́ pé Báálì ni, ẹ tẹ̀ lé e!” Àwọn èèyàn náà kò sì fèsì kankan. 22 Ni Èlíjà bá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Èmi nìkan ló kù nínú àwọn wòlíì Jèhófà,+ nígbà tí àwọn wòlíì Báálì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (450) ọkùnrin. 23 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fún wa ní akọ ọmọ màlúù méjì, kí wọ́n mú akọ ọmọ màlúù kan, kí wọ́n gé e sí wẹ́wẹ́, kí wọ́n sì kó o sórí igi, ṣùgbọ́n kí wọ́n má fi iná sí i. Èmi náà á ṣètò akọ ọmọ màlúù kejì, màá sì kó o sórí igi, ṣùgbọ́n mi ò ní fi iná sí i. 24 Lẹ́yìn náà, kí ẹ pe orúkọ ọlọ́run yín,+ èmi náà á pe orúkọ Jèhófà. Ọlọ́run tí ó bá fi iná dáhùn ni Ọlọ́run tòótọ́.”+ Gbogbo àwọn èèyàn náà bá dáhùn pé: “Ohun tí o sọ dáa.”

25 Èlíjà wá sọ fún àwọn wòlíì Báálì pé: “Ẹ mú akọ ọmọ màlúù kan, kí ẹ sì kọ́kọ́ ṣètò rẹ̀, nítorí pé ẹ̀yin ni ó pọ̀ jù. Kí ẹ wá pe orúkọ ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n kí ẹ má fi iná sí i.” 26 Torí náà, wọ́n mú akọ ọmọ màlúù tí wọ́n yàn, wọ́n ṣètò rẹ̀, wọ́n sì ń pe orúkọ Báálì láti àárọ̀ títí di ọ̀sán, wọ́n ń sọ pé: “Báálì, dá wa lóhùn!” Ṣùgbọ́n wọn ò gbọ́ ohùn kankan, ẹnì kankan ò sì dá wọn lóhùn.+ Wọ́n sì ń tiro yí ká pẹpẹ tí wọ́n ṣe. 27 Lọ́wọ́ ọ̀sán, Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Ẹ fi gbogbo ohùn yín pè é! Ṣebí ọlọ́run ni!+ Bóyá ó ti ronú lọ tàbí kó jẹ́ pé ó ti lọ yàgbẹ́.* Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ló sùn lọ, tó sì yẹ kí ẹnì kan jí i!” 28 Wọ́n ń fi gbogbo ohùn wọn kígbe, wọ́n sì ń fi ọ̀bẹ àti aṣóró ya ara wọn bí àṣà wọn, títí ẹ̀jẹ̀ fi tú jáde sí gbogbo ara wọn. 29 Nígbà tí ọ̀sán ti pọ́n, tí wọ́n sì ń ṣe wọ́nranwọ̀nran* títí di ìgbà tí a máa ń fi ọrẹ ọkà rúbọ, àmọ́ wọn kò gbọ́ ohùn kankan, ẹnì kankan kò dá wọn lóhùn, kò sì sí ẹni tó ń fiyè sí wọn.+

30 Níkẹyìn, Èlíjà sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ sún mọ́ mi.” Nítorí náà, gbogbo àwọn èèyàn náà sún mọ́ ọn. Lẹ́yìn náà, ó tún pẹpẹ Jèhófà tí wọ́n ti ya lulẹ̀ ṣe.+ 31 Ni Èlíjà bá kó òkúta méjìlá (12), tó jẹ́ iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Jékọ́bù, ẹni tí Jèhófà sọ fún pé: “Ísírẹ́lì ni orúkọ rẹ yóò máa jẹ́.”+ 32 Ó fi àwọn òkúta náà mọ pẹpẹ kan+ fún ògo orúkọ Jèhófà. Ó sì gbẹ́ kòtò kan yí pẹpẹ náà ká, àyè tó wà níbẹ̀ fẹ̀ tó ibi tí wọ́n lè fún irúgbìn òṣùwọ̀n síà* méjì sí. 33 Lẹ́yìn ìyẹn, ó to àwọn igi, ó gé akọ ọmọ màlúù náà sí wẹ́wẹ́, ó sì kó o sórí àwọn igi náà.+ Ó wá sọ pé: “Ẹ pọn omi kún ìṣà mẹ́rin tí ó tóbi, kí ẹ sì dà á sórí ẹran ẹbọ sísun náà àti àwọn igi náà.” 34 Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Ẹ ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.” Torí náà, wọ́n ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó tún sọ pé: “Ẹ ṣe é nígbà kẹta.” Torí náà, wọ́n ṣe é nígbà kẹta. 35 Omi yí pẹpẹ náà ká, ó sì tún pọn omi kún kòtò náà.

36 Ní déédéé àkókò tí wọ́n máa ń fi ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́ rúbọ,+ wòlíì Èlíjà wá síwájú, ó sì sọ pé: “Jèhófà, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Ísírẹ́lì, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti pé ìránṣẹ́ rẹ ni mí, kí wọ́n sì mọ̀ pé ìwọ lo ní kí n ṣe gbogbo nǹkan yìí.+ 37 Dá mi lóhùn, Jèhófà! Dá mi lóhùn kí àwọn èèyàn yìí lè mọ̀ pé ìwọ, Jèhófà, ni Ọlọ́run tòótọ́ àti pé o fẹ́ yí ọkàn wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ.”+

38 Ni iná Jèhófà bá bọ́ láti òkè, ó sì jó ẹran ẹbọ sísun+ náà àti àwọn igi, àwọn òkúta àti iyẹ̀pẹ̀ ibẹ̀ run, ó sì lá omi inú kòtò náà gbẹ.+ 39 Nígbà tí gbogbo àwọn èèyàn náà rí i, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n dojú bolẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́! Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!” 40 Ni Èlíjà bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbá àwọn wòlíì Báálì mú! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkankan lára wọn sá lọ!” Ní kíá, wọ́n gbá wọn mú, Èlíjà wá mú wọn lọ sí odò* Kíṣónì,+ ó sì pa wọ́n níbẹ̀.+

41 Èlíjà wá sọ fún Áhábù pé: “Gòkè lọ, kí o jẹ, kí o sì mu, nítorí ìró òjò+ ń dún.” 42 Torí náà, Áhábù gòkè lọ kí ó lè jẹ, kí ó sì mu, àmọ́ Èlíjà lọ sí orí Òkè Kámẹ́lì, ó bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó sì gbé orí rẹ̀ sáàárín eékún rẹ̀.+ 43 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, gòkè lọ kí o sì wo apá ibi tí òkun wà.” Nítorí náà, ó gòkè lọ, ó wò ó, ó sì sọ pé: “Kò sí nǹkan kan.” Ìgbà méje ni Èlíjà sọ fún un pé, “Pa dà lọ.” 44 Ní ìgbà keje, ìránṣẹ́ náà sọ pé: “Wò ó! Mo rí ìkùukùu kékeré kan bí àtẹ́lẹwọ́ èèyàn tó ń gòkè bọ̀ láti inú òkun.” Èlíjà sì sọ pé: “Lọ sọ fún Áhábù pé, ‘Di kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ! Kí o sì sọ̀ kalẹ̀ lọ kí òjò má bàa dá ọ dúró!’” 45 Láàárín àkókò yìí, ojú ọ̀run ṣú dẹ̀dẹ̀, atẹ́gùn fẹ́, òjò ńlá sì rọ̀;+ Áhábù gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì lọ sí Jésírẹ́lì.+ 46 Àmọ́, Jèhófà fún Èlíjà lágbára, ó wé* aṣọ rẹ̀ mọ́ ìbàdí, ó sì ń sáré lọ níwájú Áhábù títí dé Jésírẹ́lì.

19 Nígbà náà, Áhábù+ sọ gbogbo ohun tí Èlíjà ṣe fún Jésíbẹ́lì+ àti bí ó ṣe fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì.+ 2 Ni Jésíbẹ́lì bá rán òjíṣẹ́ kan sí Èlíjà pé: “Kí àwọn ọlọ́run fìyà jẹ mí gan-an tí mi ò bá ṣe ọ́ bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn* ní ìwòyí ọ̀la!” 3 Ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí í bà á, torí náà, ó gbéra, ó sì sá nítorí ẹ̀mí* rẹ̀.+ Ó wá sí Bíá-ṣébà+ tó jẹ́ ti Júdà,+ ó sì fi ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀. 4 Ó rin ìrìn ọjọ́ kan lọ sínú aginjù, ó dúró, ó jókòó sábẹ́ igi wíwẹ́, ó sì béèrè pé kí òun* kú. Ó sọ pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Jèhófà, gba ẹ̀mí* mi,+ nítorí mi ò sàn ju àwọn baba ńlá mi.”

5 Lẹ́yìn náà, ó dùbúlẹ̀, ó sì sùn lọ lábẹ́ igi náà. Àmọ́ lójijì, áńgẹ́lì kan fọwọ́ kàn án,+ ó sì sọ fún un pé: “Dìde, jẹun.”+ 6 Nígbà tó máa lajú, ó rí búrẹ́dì ribiti kan lórí àwọn òkúta gbígbóná níbi orí rẹ̀ àti ìgò omi. Ó jẹ, ó sì mu, lẹ́yìn náà, ó sùn pa dà. 7 Nígbà tó yá, áńgẹ́lì Jèhófà pa dà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó fọwọ́ kàn án, ó sì sọ pé: “Dìde, jẹun, nítorí ibi tí ò ń lọ jìnnà gan-an, agbára rẹ ò ní lè gbé e.” 8 Nítorí náà, ó dìde, ó jẹ, ó mu, oúnjẹ náà sì fún un lágbára láti rin ìrìn ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru títí ó fi dé Hórébù, òkè Ọlọ́run tòótọ́.+

9 Ó wọnú ihò+ kan níbẹ̀, ó sì sùn mọ́jú; sì wò ó! Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó sọ fún un pé: “Kí lò ń ṣe níbí, Èlíjà?” 10 Ó fèsì pé: “Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun+ gbà mí lọ́kàn ni; nítorí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti pa májẹ̀mú rẹ tì,+ wọ́n ti ya àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ,+ èmi nìkan ló sì ṣẹ́ kù. Ní báyìí, bí wọ́n ṣe máa gba ẹ̀mí* mi ni wọ́n ń wá.”+ 11 Àmọ́, ó sọ pé: “Jáde, kí o sì dúró sórí òkè níwájú Jèhófà.” Sì wò ó! Jèhófà ń kọjá lọ,+ ẹ̀fúùfù ńlá tó lágbára ń ya àwọn òkè, ó sì ń fọ́ àwọn àpáta níwájú Jèhófà,+ àmọ́ Jèhófà kò sí nínú ẹ̀fúùfù náà. Lẹ́yìn ẹ̀fúùfù náà, ìmìtìtì ilẹ̀+ wáyé, àmọ́ Jèhófà kò sí nínú ìmìtìtì ilẹ̀ náà. 12 Lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ náà, iná sọ,+ àmọ́ Jèhófà kò sí nínú iná náà. Lẹ́yìn iná náà, ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kan sọ̀rọ̀.+ 13 Bí Èlíjà ṣe gbọ́ báyìí, ó fi ẹ̀wù oyè rẹ̀ wé ojú,+ ó jáde, ó sì dúró sí ẹnu ọ̀nà ihò náà. Ohùn kan wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí lò ń ṣe níbí, Èlíjà?” 14 Ó fèsì pé: “Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun gbà mí lọ́kàn ni; nítorí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti pa májẹ̀mú rẹ tì,+ wọ́n ti ya àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ, èmi nìkan ló sì ṣẹ́ kù. Ní báyìí, bí wọ́n ṣe máa gba ẹ̀mí* mi ni wọ́n ń wá.”+

15 Jèhófà sọ fún un pé: “Pa dà, lọ sí aginjù Damásíkù. Tí o bá débẹ̀, fi òróró yan Hásáẹ́lì+ ṣe ọba lórí Síríà. 16 Kí o fòróró yan Jéhù+ ọmọ ọmọ Nímúṣì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì, kí o sì yan Èlíṣà* ọmọ Ṣáfátì láti Ebẹli-méhólà ṣe wòlíì ní ipò rẹ.+ 17 Ẹni tó bá bọ́ lọ́wọ́ idà Hásáẹ́lì,+ Jéhù yóò pa á;+ ẹni tó bá sì bọ́ lọ́wọ́ idà Jéhù, Èlíṣà yóò pa á.+ 18 Mo ṣì ní ẹgbẹ̀rún méje (7,000) èèyàn ní Ísírẹ́lì,+ tí gbogbo wọn ò kúnlẹ̀ fún Báálì,+ tí wọn ò sì fẹnu kò ó lẹ́nu.”+

19 Torí náà, ó kúrò níbẹ̀, ó sì rí Èlíṣà ọmọ Ṣáfátì níbi tó ti ń fi àwọn akọ màlúù tí wọ́n dì ní méjì-méjì sọ́nà méjìlá (12) túlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì wà pẹ̀lú ìkejìlá. Nítorí náà, Èlíjà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ju ẹ̀wù oyè rẹ̀+ sí i lọ́rùn. 20 Ni ó bá fi àwọn akọ màlúù náà sílẹ̀, ó sì sáré tẹ̀ lé Èlíjà, ó sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ fẹnu ko bàbá àti ìyá mi lẹ́nu. Lẹ́yìn náà, màá tẹ̀ lé ọ.” Ó dá a lóhùn pé: “Pa dà lọ, kí nìdí tí màá fi dá ọ dúró?” 21 Nítorí náà, ó pa dà lọ, ó mú akọ màlúù méjì, ó pa wọ́n,* ó sì fi ọ̀pá ohun èlò ìtúlẹ̀ náà se ẹran wọn, ó fún àwọn èèyàn náà, wọ́n sì jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó gbéra, ó tẹ̀ lé Èlíjà, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.+

20 Nígbà náà, Bẹni-hádádì+ ọba Síríà+ kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n (32) pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn; ó jáde lọ, ó dó ti+ Samáríà,+ ó sì gbéjà kò ó. 2 Lẹ́yìn náà, ó rán àwọn òjíṣẹ́ sí Áhábù+ ọba Ísírẹ́lì nínú ìlú náà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ohun tí Bẹni-hádádì sọ nìyí, 3 ‘Fàdákà àti wúrà rẹ jẹ́ tèmi, àwọn ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ tó dára jù lọ sì jẹ́ tèmi.’” 4 Ọba Ísírẹ́lì bá fèsì pé: “Olúwa mi ọba, bí o ṣe sọ, èmi àti gbogbo ohun tí mo ní jẹ́ tìrẹ.”+

5 Nígbà tó yá, àwọn òjíṣẹ́ náà pa dà wá, wọ́n sọ pé: “Ohun tí Bẹni-hádádì sọ nìyí, ‘Mo ránṣẹ́ sí ọ pé: “Kí o fún mi ní fàdákà rẹ àti wúrà rẹ àti àwọn ìyàwó rẹ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ.” 6 Àmọ́ ní ìwòyí ọ̀la, màá rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ, wọn á sì fara balẹ̀ wá inú ilé rẹ àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gbogbo nǹkan rẹ tó ṣeyebíye ni wọ́n á gbà, tí wọ́n á sì kó lọ.’”

7 Ni ọba Ísírẹ́lì bá pe gbogbo àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà, ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ rí i pé wàhálà ni ọkùnrin yìí fẹ́ dá sílẹ̀, ó ní kí n fún òun ní àwọn ìyàwó mi, àwọn ọmọ mi, fàdákà mi àti wúrà mi, mi ò sì jiyàn.” 8 Gbogbo àwọn àgbààgbà àti gbogbo àwọn èèyàn náà wá sọ fún un pé: “Má dá a lóhùn, má sì gbà fún un.” 9 Torí náà, ó sọ fún àwọn òjíṣẹ́ Bẹni-hádádì pé: “Ẹ sọ fún olúwa mi ọba pé, ‘Gbogbo ohun tí o kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni màá ṣe, àmọ́ ní ti eléyìí, mi ò lè ṣe é.’” Àwọn òjíṣẹ́ náà bá gbéra, wọ́n sì lọ jíṣẹ́ fún un.

10 Bẹni-hádádì wá ránṣẹ́ sí i pé: “Kí àwọn ọlọ́run fìyà jẹ mí gan-an tí iyẹ̀pẹ̀ tó máa ṣẹ́ kù sí Samáríà bá máa kún ọwọ́ àwọn tó tẹ̀ lé mi!” 11 Ọba Ísírẹ́lì dáhùn pé: “Ẹ sọ fún un pé, ‘Kí ẹni tó ń dira ogun má ṣe fọ́nnu bí ẹni tó ti togun dé.’”+ 12 Gbàrà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, bí òun àti àwọn ọba ṣe ń mutí nínú àwọn àgọ́* wọn, ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ gbára dì!” Torí náà, wọ́n gbára dì láti gbéjà ko ìlú náà.

13 Àmọ́ wòlíì kan wá bá Áhábù+ ọba Ísírẹ́lì, ó sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ṣé o rí gbogbo èèyàn rẹpẹtẹ yìí? Màá fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ lónìí, wàá sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”+ 14 Áhábù bá béèrè pé: “Ta ló máa lò?” ó fèsì pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Àwọn ìránṣẹ́ àwọn olórí tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀* ni.’” Torí náà, ó béèrè pé: “Ta ló máa kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ogun náà?” ó fèsì pé: “Ìwọ ni!”

15 Áhábù wá ka iye àwọn ìránṣẹ́ àwọn olórí tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀, wọ́n jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (232); lẹ́yìn náà, ó ka gbogbo àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje (7,000). 16 Wọ́n jáde lọ ní ọ̀sán gangan nígbà tí Bẹni-hádádì ti rọ ara rẹ̀ yó nínú àwọn àgọ́* pẹ̀lú àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n (32) tó ń ràn án lọ́wọ́. 17 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ àwọn olórí tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ kọ́kọ́ jáde, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Bẹni-hádádì rán àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀, wọ́n sì pa dà wá ròyìn fún un pé: “Àwọn ọkùnrin kan ti wá láti Samáríà.” 18 Ni ó bá sọ pé: “Tó bá jẹ́ àlàáfíà ni wọ́n bá wá, ẹ mú wọn láàyè; tó bá sì jẹ́ pé ogun ni wọ́n bá wá, ẹ mú wọn láàyè.” 19 Àmọ́ nígbà tí àwọn yìí jáde wá láti inú ìlú, ìyẹn àwọn ìránṣẹ́ àwọn olórí tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun tó ń tẹ̀ lé wọn, 20 kálukú pa ẹni tó dojú kọ ọ́. Ni àwọn ará Síríà bá fẹsẹ̀ fẹ,+ Ísírẹ́lì sì gbá tẹ̀ lé wọn, àmọ́ Bẹni-hádádì ọba Síríà gun ẹṣin sá lọ pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn agẹṣin. 21 Àmọ́ ọba Ísírẹ́lì jáde lọ, ó ń ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tó ń gun ẹṣin àti àwọn tó wà lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin, ó sì ṣẹ́gun àwọn ará Síríà lọ́nà tó kàmàmà.*

22 Nígbà tó yá, wòlíì náà+ wá sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì, ó sọ fún un pé: “Lọ gbára dì, kí o sì ro ohun tí o máa ṣe,+ torí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún* tó ń bọ̀, ọba Síríà máa wá gbéjà kò ọ́.”+

23 Nígbà náà, àwọn ìránṣẹ́ ọba Síríà sọ fún un pé: “Ọlọ́run wọn jẹ́ Ọlọ́run àwọn òkè. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi borí wa. Àmọ́, tí a bá bá wọn jà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú, a ó borí wọn. 24 Ohun tí o tún máa ṣe ni pé: Yọ àwọn ọba kúrò+ ní ipò wọn, kí o sì fi àwọn gómìnà rọ́pò wọn. 25 Lẹ́yìn náà, kó* àwọn ọmọ ogun tí iye wọn jẹ́ iye ọmọ ogun tí o pàdánù jọ àti àwọn ẹṣin pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí iye wọn jẹ́ iye tí o ti pàdánù. Jẹ́ kí a bá wọn jà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú, ó dájú pé a máa borí wọn.” Torí náà, ó gba ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un, ó sì ṣe ohun tí wọ́n sọ.

26 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún,* Bẹni-hádádì kó àwọn ará Síríà jọ, ó sì lọ sí Áfékì+ láti bá Ísírẹ́lì jà. 27 Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì náà kóra jọ, a pèsè nǹkan fún wọn, wọ́n sì jáde lọ pàdé wọn. Nígbà tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì dó síwájú wọn, wọ́n dà bí agbo ewúrẹ́ méjì tó kéré, àmọ́ àwọn ará Síríà gba gbogbo ilẹ̀ kan.+ 28 Ìgbà náà ni èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sún mọ́ ọba Ísírẹ́lì, ó sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Nítorí àwọn ará Síríà sọ pé: “Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run àwọn òkè, kì í ṣe Ọlọ́run pẹ̀tẹ́lẹ̀,” màá fi gbogbo èèyàn rẹpẹtẹ yìí lé ọ lọ́wọ́,+ wàá sì mọ̀ dájú pé èmi ni Jèhófà.’”+

29 Ọjọ́ méje ni wọ́n fi wà ní ibùdó, àwùjọ méjèèjì sì dojú kọra. Ní ọjọ́ keje, ìjà náà bẹ̀rẹ̀. Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì pa ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) àwọn ọmọ ogun Síríà tó ń fẹsẹ̀ rìn, ní ọjọ́ kan. 30 Àwọn tó ṣẹ́ kù sá lọ sí Áfékì,+ sínú ìlú náà. Àmọ́ ògiri wó lu ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27,000) ọkùnrin tó ṣẹ́ kù. Bẹni-hádádì náà fẹsẹ̀ fẹ, ó sì wá sínú ìlú náà, ó wá fara pa mọ́ sínú yàrá inú.

31 Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilé Ísírẹ́lì máa ń lójú àánú.* Jọ̀wọ́, jẹ́ ká sán aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́ ìdí, kí a wé okùn mọ́ orí wa, kí a sì jáde lọ bá ọba Ísírẹ́lì. Bóyá ó máa dá ẹ̀mí* rẹ sí.”+ 32 Torí náà, wọ́n sán aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́ ìdí, wọ́n wé okùn mọ́ orí, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì, wọ́n sọ pé: “Ìránṣẹ́ rẹ Bẹni-hádádì sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, dá ẹ̀mí* mi sí.’” Ó fèsì pé: “Ṣé ó ṣì wà láàyè? Arákùnrin mi ni.” 33 Àwọn ọkùnrin náà kà á sí àmì, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, torí náà wọ́n sọ pé: “Arákùnrin rẹ ni Bẹni-hádádì.” Ni ó bá sọ pé: “Ẹ lọ mú un wá.” Lẹ́yìn náà, Bẹni-hádádì jáde wá bá a, ó sì ní kí ó gòkè sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin.

34 Bẹni-hádádì wá sọ fún un pé: “Màá dá àwọn ìlú tí bàbá mi gbà lọ́wọ́ bàbá rẹ pa dà, kí o lè kọ́ àwọn ilé ìtajà sí* Damásíkù, bí bàbá mi ti ṣe ní Samáríà.”

Áhábù fèsì pé: “Nítorí àdéhùn* yìí, màá jẹ́ kí o lọ.”

Lẹ́yìn náà, ó bá a ṣàdéhùn, ó sì jẹ́ kí ó lọ.

35 Jèhófà bá ọ̀kan lára àwọn ọmọ wòlíì* sọ̀rọ̀,+ ni ó bá sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, lù mí.” Àmọ́ ọkùnrin náà kọ̀, kò lù ú. 36 Nítorí náà, ó sọ fún un pé: “Torí pé o kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà, gbàrà tí o bá ti kúrò lọ́dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ.”* Lẹ́yìn tí ó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan yọ sí i, ó sì pa á.

37 Ó rí ọkùnrin míì, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, lù mí.” Torí náà, ọkùnrin náà lù ú, ó sì ṣe é léṣe.

38 Wòlíì náà wá lọ dúró de ọba lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ó sì fi ọ̀já tí wọ́n fi ń di ọgbẹ́ bo ojú, kí wọ́n má bàa dá a mọ̀. 39 Bí ọba ṣe ń kọjá lọ, ó ké sí ọba pé: “Ìránṣẹ́ rẹ jáde lọ sí ibi tí ogun ti le, ọkùnrin kan ń jáde bọ̀ tó mú ọkùnrin mìíràn wá bá mi, ó sì sọ pé, ‘Máa ṣọ́ ọkùnrin yìí. Tí ó bá sá lọ, tálẹ́ńtì* fàdákà kan ni wàá san tàbí kí o fi ẹ̀mí rẹ dí ẹ̀mí rẹ̀.’*+ 40 Àmọ́ nígbà tí ọwọ́ èmi ìránṣẹ́ rẹ dí gan-an, kí n tó mọ̀, ọkùnrin náà ti lọ.” Ọba Ísírẹ́lì wá sọ fún un pé: “Bí ìdájọ́ rẹ ṣe máa rí náà nìyẹn; o ti fúnra rẹ ṣèdájọ́.” 41 Ni ó bá tètè yọ ọ̀já tí wọ́n fi ń di ọgbẹ́ kúrò lójú rẹ̀, ọba Ísírẹ́lì wá dá a mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn wòlíì ni.+ 42 Ó sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Nítorí o jẹ́ kí ọkùnrin tí mo ní ikú tọ́ sí sá mọ́ ọ lọ́wọ́,+ ẹ̀mí rẹ ló máa dí ẹ̀mí rẹ̀,*+ àwọn èèyàn rẹ á sì dípò àwọn èèyàn rẹ̀.’”+ 43 Ni ọba Ísírẹ́lì bá lọ sí ilé rẹ̀ ní Samáríà,+ ó dì kunkun, ó sì dorí kodò.

21 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọ̀ràn kan ṣẹlẹ̀ tó dá lórí ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì. Ọgbà náà wà ní Jésírẹ́lì+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààfin Áhábù ọba Samáríà. 2 Áhábù sọ fún Nábótì pé: “Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ kí n lè fi ṣe ibi tí màá máa gbin nǹkan sí torí pé ẹ̀gbẹ́ ilé mi ló wà. Màá fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó dára ju ìyẹn lọ láti fi rọ́pò rẹ̀. Tí o bá sì fẹ́, màá fún ọ ní owó rẹ̀.” 3 Àmọ́ Nábótì sọ fún Áhábù pé: “Jèhófà ò ní fẹ́ gbọ́ rárá pé mo fi ogún àwọn baba ńlá mi+ fún ọ.” 4 Torí náà, Áhábù wá sínú ilé rẹ̀, ó dì kunkun, ó sì dorí kodò nítorí èsì tí Nábótì ará Jésírẹ́lì fún un, nígbà tó sọ pé: “Mi ò ní fún ọ ní ogún àwọn baba ńlá mi.” Ó wá dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀, ó gbé ojú sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó kọ̀, kò jẹun.

5 Jésíbẹ́lì+ ìyàwó rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí inú rẹ fi bà jẹ́* débi pé o ò jẹun?” 6 Ó dá a lóhùn pé: “Torí mo sọ fún Nábótì ará Jésírẹ́lì pé, ‘Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ kí n san owó rẹ̀. Tí o bá sì fẹ́, jẹ́ kí n fún ọ ní ọgbà àjàrà míì dípò rẹ̀.’ Àmọ́, ó sọ pé, ‘Mi ò ní fún ọ ní ọgbà àjàrà mi.’” 7 Jésíbẹ́lì ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Ìwọ kọ́ lò ń ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì ni? Dìde, jẹun, kí o sì jẹ́ kí inú rẹ dùn. Màá fún ọ ní ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì.”+ 8 Torí náà, ó kọ àwọn lẹ́tà ní orúkọ Áhábù, ó gbé èdìdì ọba+ lé e, ó sì fi àwọn lẹ́tà náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbààgbà+ àti àwọn èèyàn pàtàkì tó ń gbé ní ìlú Nábótì. 9 Ó kọ ọ́ sínú àwọn lẹ́tà náà pé: “Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì ní kí Nábótì jókòó sí iwájú gbogbo àwọn èèyàn náà. 10 Kí ẹ ní kí ọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ aláìníláárí jókòó síwájú rẹ̀, kí wọ́n sì ta kò ó+ pé, ‘O ti sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti sí ọba!’+ Lẹ́yìn náà, kí ẹ mú un jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.”+

11 Torí náà, àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀, àwọn àgbààgbà àti àwọn èèyàn pàtàkì tó ń gbé ìlú rẹ̀ ṣe ohun tó wà nínú lẹ́tà tí Jésíbẹ́lì fi ránṣẹ́ sí wọn. 12 Wọ́n kéde ààwẹ̀, wọ́n sì ní kí Nábótì jókòó síwájú gbogbo àwọn èèyàn náà. 13 Ni méjì lára àwọn ọkùnrin aláìníláárí bá wọlé, wọ́n jókòó síwájú rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ta ko Nábótì níwájú àwọn èèyàn náà, wọ́n ní: “Nábótì ti sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti sí ọba!”+ Lẹ́yìn náà, wọ́n mú un lọ sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa.+ 14 Wọ́n wá ránṣẹ́ sí Jésíbẹ́lì pé: “A ti sọ Nábótì lókùúta pa.”+

15 Gbàrà tí Jésíbẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti sọ Nábótì lókùúta pa, ó sọ fún Áhábù pé: “Dìde, lọ gba ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì,+ tí ó kọ̀ láti tà fún ọ, nítorí Nábótì kò sí láàyè mọ́. Ó ti kú.” 16 Bí Áhábù ṣe gbọ́ pé Nábótì ti kú, ó dìde, ó sì lọ sí ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì láti gbà á.

17 Àmọ́ Jèhófà bá Èlíjà+ ará Tíṣíbè sọ̀rọ̀, ó ní: 18 “Dìde, lọ pàdé Áhábù ọba Ísírẹ́lì tó wà ní Samáríà.+ Ó wà nínú ọgbà àjàrà Nábótì, níbi tí ó ti lọ gbà á. 19 Kí o sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “O ti pa ọkùnrin yìí+ o sì ti sọ nǹkan ìní rẹ̀ di tìrẹ,* àbí?”’+ Kí o wá sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ibi tí àwọn ajá ti lá ẹ̀jẹ̀ Nábótì, ni àwọn ajá ti máa lá ẹ̀jẹ̀ rẹ.”’”+

20 Áhábù sọ fún Èlíjà pé: “O ti wá mi kàn, ìwọ ọ̀tá mi!”+ Ó dáhùn pé: “Mo ti wá ọ kàn. ‘Nítorí o ti pinnu* láti máa ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ 21 màá mú àjálù bá ọ, màá gbá ọ dà nù bí ẹni gbálẹ̀, màá sì pa gbogbo ọkùnrin* ilé Áhábù run,+ títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì.+ 22 Màá sì ṣe ilé rẹ bí ilé Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì àti bí ilé Bááṣà+ ọmọ Áhíjà, nítorí o ti mú mi bínú, o sì ti mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.’ 23 Ní ti Jésíbẹ́lì, Jèhófà sọ pé: ‘Àwọn ajá ló máa jẹ Jésíbẹ́lì lórí ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì.+ 24 Èèyàn Áhábù èyíkéyìí tí ó bá kú sí ìlú ni àwọn ajá yóò jẹ, èyí tí ó bá sì kú sí pápá ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ.+ 25 Ó dájú pé kò sí ẹni tó dà bí Áhábù,+ ẹni tó ti pinnu* láti máa ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, ẹni tí Jésíbẹ́lì+ ìyàwó rẹ̀ ń tì gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n. 26 Ó hùwà ìríra tó burú jáì, torí ó tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin,* bí gbogbo àwọn Ámórì ti ṣe, àwọn tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”+

27 Bí Áhábù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó fa ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, ó sì gbé aṣọ ọ̀fọ̀* wọ̀; ó gbààwẹ̀, ó ń sùn lórí aṣọ ọ̀fọ̀,* ó sì ń rìn kiri nínú ìbànújẹ́. 28 Nígbà náà, Jèhófà bá Èlíjà ará Tíṣíbè sọ̀rọ̀, ó ní: 29 “Ṣé o rí bí Áhábù ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítorí mi?+ Torí pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi, mi ò ní mú àjálù náà wá nígbà ayé rẹ̀. Ìgbà ayé ọmọ rẹ̀ ni màá mú àjálù náà wá sórí ilé rẹ̀.”+

22 Ọdún mẹ́ta gbáko ni kò fi sí ogun láàárín Síríà àti Ísírẹ́lì. 2 Ní ọdún kẹta, Jèhóṣáfátì ọba+ Júdà lọ sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì.+ 3 Ìgbà náà ni ọba Ísírẹ́lì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé àwa la ni Ramoti-gílíádì?+ Síbẹ̀, à ń wò, a ò ṣe nǹkan kan láti gbà á lọ́wọ́ ọba Síríà.” 4 Ó wá sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ṣé wàá tẹ̀ lé mi lọ jà ní Ramoti-gílíádì?” Jèhóṣáfátì dá ọba Ísírẹ́lì lóhùn pé: “Ìkan náà ni èmi àti ìwọ. Ìkan náà ni àwọn èèyàn mi àti àwọn èèyàn rẹ. Ìkan náà sì ni àwọn ẹṣin mi àti àwọn ẹṣin rẹ.”+

5 Àmọ́, Jèhóṣáfátì sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Jọ̀wọ́, kọ́kọ́ wádìí ọ̀rọ̀+ lọ́dọ̀ Jèhófà.”+ 6 Torí náà, ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì jọ, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin, ó sì bi wọ́n pé: “Ṣé kí n lọ bá Ramoti-gílíádì jà tàbí kí n má lọ?” Wọ́n dá a lóhùn pé: “Lọ, Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”

7 Jèhóṣáfátì wá sọ pé: “Ṣé kò sí wòlíì Jèhófà níbí ni? Ẹ jẹ́ ká tún wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀.”+ 8 Ni ọba Ísírẹ́lì bá sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ọkùnrin kan ṣì wà tí a lè ní kó bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà;+ ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀,+ nítorí kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi ibi.+ Mikáyà ni orúkọ rẹ̀, ọmọ Ímílà ni.” Síbẹ̀, Jèhóṣáfátì sọ pé: “Kí ọba má sọ bẹ́ẹ̀.”

9 Torí náà, ọba Ísírẹ́lì pe òṣìṣẹ́ ààfin kan, ó sì sọ fún un pé: “Lọ pe Mikáyà ọmọ Ímílà wá kíákíá.”+ 10 Lásìkò náà, ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà wà ní ìjókòó, kálukú lórí ìtẹ́ rẹ̀, wọ́n wọ ẹ̀wù oyè, wọ́n sì wà ní ibi ìpakà tó wà ní àtiwọ ẹnubodè Samáríà, gbogbo àwọn wòlíì sì ń sọ tẹ́lẹ̀ níwájú wọn.+ 11 Ìgbà náà ni Sedekáyà ọmọ Kénáánà ṣe àwọn ìwo irin fún ara rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ohun tí o máa fi kan* àwọn ará Síríà pa nìyí títí wàá fi pa wọ́n run.’” 12 Ohun kan náà ni gbogbo àwọn wòlíì tó kù ń sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n ń sọ pé: “Lọ sí Ramoti-gílíádì, wàá ṣẹ́gun; Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”

13 Òjíṣẹ́ tó lọ pe Mikáyà sọ fún un pé: “Wò ó! Ohun rere ni àwọn wòlíì ń sọ fún ọba, ọ̀rọ̀ wọn kò ta kora. Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí o sì sọ ohun rere.”+ 14 Ṣùgbọ́n Mikáyà sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ohun tí Jèhófà bá sọ fún mi ni màá sọ.” 15 Lẹ́yìn náà, ó wọlé sọ́dọ̀ ọba, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Mikáyà, ṣé ká lọ bá Ramoti-gílíádì jà àbí ká má lọ?” Lójú ẹsẹ̀, ó fèsì pé: “Lọ, wàá ṣẹ́gun; Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.” 16 Ni ọba bá sọ fún un pé: “Ìgbà mélòó ni màá ní kí o búra pé òótọ́ lo máa sọ fún mi ní orúkọ Jèhófà?” 17 Nítorí náà, ó sọ pé: “Mo rí i tí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tú ká lórí àwọn òkè,+ bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́. Jèhófà sọ pé: ‘Àwọn yìí kò ní ọ̀gá. Kí kálukú pa dà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’”

18 Nígbà náà, ọba Ísírẹ́lì sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé, ‘Kò ní sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi, àfi ibi’?”+

19 Mikáyà bá sọ pé: “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: Mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀,+ gbogbo ọmọ ogun ọ̀run sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, lápá ọ̀tún àti lápá òsì.+ 20 Jèhófà sì sọ pé, ‘Ta ló máa tan Áhábù, kí ó lè lọ kí ó sì kú ní Ramoti-gílíádì?’ Ẹni tibí ń sọ báyìí, ẹni tọ̀hún sì ń sọ nǹkan míì. 21 Ni ẹ̀mí* kan+ bá jáde wá, ó dúró níwájú Jèhófà, ó sì sọ pé, ‘Màá tàn án.’ Jèhófà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘Báwo lo ṣe máa ṣe é?’ 22 Ó dáhùn pé, ‘Màá jáde lọ, màá sì di ẹ̀mí tó ń tanni jẹ ní ẹnu gbogbo wòlíì rẹ̀.’+ Torí náà, ó sọ pé, ‘O máa tàn án, kódà, wàá ṣe àṣeyọrí. Lọ, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ 23 Wò ó, Jèhófà ti fi ẹ̀mí tó ń tanni jẹ sí ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ yìí,+ àmọ́ àjálù ni Jèhófà sọ pé ó máa bá ọ.”+

24 Sedekáyà ọmọ Kénáánà wá sún mọ́ tòsí, ó sì gbá Mikáyà létí, ó sọ pé: “Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Jèhófà gbà kúrò lára mi tó fi wá bá ọ sọ̀rọ̀?”+ 25 Mikáyà dá a lóhùn pé: “Wò ó! Wàá rí ọ̀nà tó gbà lọ́jọ́ tí o máa lọ sá pa mọ́ sí yàrá inú lọ́hùn-ún.” 26 Ìgbà náà ni ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Mú Mikáyà, kí o sì fà á lé ọwọ́ Ámọ́nì olórí ìlú àti Jóáṣì ọmọ ọba. 27 Kí o sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí ọba sọ nìyí: “Ẹ fi ọ̀gbẹ́ni yìí sínú ẹ̀wọ̀n,+ kí ẹ sì máa fún un ní oúnjẹ díẹ̀ àti omi díẹ̀, títí màá fi dé ní àlàáfíà.”’” 28 Àmọ́ Mikáyà sọ pé: “Tí o bá pa dà ní àlàáfíà, á jẹ́ pé Jèhófà kò bá mi sọ̀rọ̀.”+ Ó tún sọ pé: “Ẹ fọkàn sí i o, gbogbo ẹ̀yin èèyàn.”

29 Ni ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà bá lọ sí Ramoti-gílíádì.+ 30 Ọba Ísírẹ́lì sì sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Màá para dà, màá sì lọ sójú ogun, ṣùgbọ́n ní tìrẹ, wọ ẹ̀wù oyè rẹ.” Torí náà, ọba Ísírẹ́lì para dà,+ ó sì bọ́ sójú ogun. 31 Ọba Síríà ti pàṣẹ fún àwọn méjìlélọ́gbọ̀n (32) tó jẹ́ olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pé:+ “Ẹ má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà, ì báà jẹ́ ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, àfi ọba Ísírẹ́lì.” 32 Gbàrà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí Jèhóṣáfátì, wọ́n sọ lọ́kàn ara wọn pé: “Ó dájú pé ọba Ísírẹ́lì nìyí.” Nítorí náà, wọ́n yíjú sí i láti bá a jà; Jèhóṣáfátì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. 33 Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí i pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n pa dà lẹ́yìn rẹ̀.

34 Àmọ́, ọkùnrin kan ṣàdédé ta ọfà rẹ̀,* ó sì ba ọba Ísírẹ́lì láàárín ibi tí ẹ̀wù irin rẹ̀ ti so pọ̀. Torí náà, ọba sọ fún ẹni tó ń wa kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pé: “Yí pa dà, kí o sì gbé mi jáde kúrò lójú ogun,* nítorí mo ti fara gbọgbẹ́ gan-an.”+ 35 Ìjà náà le gan-an jálẹ̀ ọjọ́ yẹn, kódà wọ́n ní láti gbé ọba nàró nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ará Síríà jà. Ẹ̀jẹ̀ ọgbẹ́ náà ń dà jáde sínú kẹ̀kẹ́ ogun náà, ó sì kú ní ìrọ̀lẹ́.+ 36 Nígbà tí oòrùn ń wọ̀, ìkéde kan wáyé káàkiri ibùdó pé: “Kí kálukú lọ sí ìlú rẹ̀! Kí kálukú sì lọ sí ilẹ̀ rẹ̀!”+ 37 Bí ọba ṣe kú nìyẹn, wọ́n gbé e wá sí Samáríà, wọ́n sì sin ín sí Samáríà. 38 Nígbà tí wọ́n fọ kẹ̀kẹ́ ogun náà létí adágún odò tó wà ní Samáríà, àwọn ajá lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn aṣẹ́wó sì wẹ̀ níbẹ̀,* gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ.+

39 Ní ti ìyókù ìtàn Áhábù àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti ilé* tó fi eyín erin kọ́+ àti gbogbo ìlú tí ó kọ́, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn àwọn ọba Ísírẹ́lì? 40 Níkẹyìn, Áhábù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ Ahasáyà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

41 Jèhóṣáfátì+ ọmọ Ásà di ọba lórí Júdà ní ọdún kẹrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì. 42 Ẹni ọdún márùndínlógójì (35) ni Jèhóṣáfátì nígbà tó jọba, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ásúbà ọmọ Ṣílíháì. 43 Ó ń rìn ní gbogbo ọ̀nà Ásà+ bàbá rẹ̀. Kò yà kúrò nínú rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà.+ Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò, àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.+ 44 Jèhóṣáfátì ń ṣe ohun tí á jẹ́ kí àlàáfíà máa wà láàárín òun àti ọba Ísírẹ́lì.+ 45 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóṣáfátì àti àwọn nǹkan ńlá tó gbé ṣe àti bí ó ṣe jagun, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn àwọn ọba Júdà? 46 Ó tún lé ìyókù àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin tó wà ní tẹ́ńpìlì+ jáde ní ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù nígbà ayé Ásà bàbá rẹ̀.+

47 Nígbà náà, kò sí ọba ní Édómù;+ ìjòyè kan ló wà nípò ọba.+

48 Jèhóṣáfátì tún ṣe àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì* láti máa fi kó wúrà+ wá láti Ófírì, ṣùgbọ́n wọn ò lè lọ torí pé àwọn ọkọ̀ òkun náà fọ́ ní Esioni-gébérì.+ 49 Ìgbà náà ni Ahasáyà ọmọ Áhábù sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Jẹ́ kì àwọn ìránṣẹ́ mi bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ nínú àwọn ọkọ̀ òkun náà,” ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì kò gbà.

50 Níkẹyìn, Jèhóṣáfátì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì baba ńlá rẹ̀; Jèhórámù+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

51 Ahasáyà+ ọmọ Áhábù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà lọ́dún kẹtàdínlógún Jèhóṣáfátì ọba Júdà, ó sì fi ọdún méjì ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì. 52 Ó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, ó sì ń rìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀+ àti ti ìyá rẹ̀+ àti ní ọ̀nà Jèróbóámù ọmọ Nébátì, ẹni tó mú kí Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀.+ 53 Ó ń sin Báálì+ nìṣó, ó ń forí balẹ̀ fún un, ó sì ń mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ bínú bí bàbá rẹ̀ ti ṣe.

Ní Héb., “ọjọ́.”

Ìyẹn, ẹni tí kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí.

Tàbí “ṣe ohun tó máa bà á nínú jẹ́; bá a wí.”

Tàbí “ọkàn rẹ àti ọkàn.”

Tàbí “ra ọkàn mi pa dà.”

Tàbí “abo ìbaaka.”

Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.

Tàbí “mi ilẹ̀ tìtì.”

Tàbí “iyì.”

Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.

Ní Héb., “Mò ń lọ ní ọ̀nà gbogbo ayé.”

Tàbí “hùwà ọgbọ́n.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Ní Héb., “kò sígbà tí a máa ké ọkùnrin kan láti ọ̀dọ̀ rẹ kúrò.”

Ní Héb., “Má ṣe jẹ́ kí ewú rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù ní àlàáfíà”; Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ṣìọ́ọ̀lù.”

Ní Héb., “mú kí ewú rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.”

Ní Héb., “Àwọn ọjọ́.”

Ní Héb., “fi ojú wọn sára mi.”

Tàbí “gba ọkàn.”

Tàbí “sọ ìdílé mi di ìdílé tó ń jọba.”

Tàbí “ó kọ lu Ádóníjà.”

Tàbí “àtọmọdọ́mọ.”

Tàbí “àtọmọdọ́mọ.”

Tàbí “di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì.”

Tàbí “mú.”

Ní Héb., “tí ó tóbi.”

Tàbí “ọmọ kékeré.”

Ní Héb., “mi ò mọ bí a ṣe ń jáde àti bí a ṣe ń wọlé.”

Tàbí kó jẹ́, “tó ṣòro.” Ní Héb., “tó wúwo.”

Ní Héb., “ọjọ́ púpọ̀.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ìgbésí ayé.”

Ní Héb., “ọjọ́ gígùn.”

Ní Héb., “ẹ̀rù ọba sì bà wọ́n.”

Tàbí “olórí.”

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Tàbí “owó òde.”

Kọ́ọ̀ kan jẹ́ Lítà 220. Wo Àfikún B14.

Ìyẹn, ìwọ̀ oòrùn odò Yúfírétì.

Iye yìí wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan àti ní àwọn apá míì tí ìtàn yìí ti fara hàn nínú Bíbélì. Àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì pe iye yìí ní ọ̀kẹ́ méjì (40,000).

Tàbí “agẹṣin.”

Ní Héb., “ọkàn tó gbòòrò.”

Tàbí “pa.”

Tàbí “àwọn ẹ̀dá tó ń fò.”

Ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹranko afàyàfà àti àwọn kòkòrò wà lára wọn.

Tàbí “nífẹ̀ẹ́.”

Tàbí “èèyàn tó pọ̀ níye.”

Kọ́ọ̀ kan jẹ́ Lítà 220. Wo Àfikún B14.

Tàbí “wíìtì.”

Ní Héb., “òróró tí a fún.”

Tàbí “dá májẹ̀mú.”

Tàbí “àwọn tó ń ru ẹrù.”

Wo Àfikún B15.

Wo Àfikún B8.

Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Tàbí “Gọ̀bì.”

Ní Héb., “tẹ́ńpìlì ilé.”

Tàbí “fífẹ̀.”

Tàbí “ó jẹ́ 20 ìgbọ̀nwọ́ lára fífẹ̀ ilé náà.”

Tàbí “wíńdò.”

Tàbí “Ó ṣe àwọn fèrèsé tó kéré lápá kan tó sì fẹ̀ lódìkejì.”

Ibi Mímọ́ ni ibí yìí ń tọ́ka sí.

Tàbí “ó ṣe àwọn ipele sára.”

Ní Héb., “lápá ọ̀tún.”

Ni Héb., “kọ́.”

Ìyẹn, nínú ilé náà.

Ìyẹn, Ibi Mímọ́ tó wà ní iwájú Ibi Mímọ́ Jù Lọ.

Ní Héb., “igi olóròóró,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Aleppo pine.

Ìyẹn, Ibi Mímọ́ Jù Lọ.

Ní Héb., “yàrá inú àti tòde.”

Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí fífẹ̀ férémù ilẹ̀kùn tàbí fífẹ̀ àwọn ilẹ̀kùn náà.

Ibi Mímọ́ ni ibí yìí ń tọ́ka sí.

Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí fífẹ̀ férémù ilẹ̀kùn tàbí fífẹ̀ àwọn ilẹ̀kùn náà.

Wo Àfikún B15.

Wo Àfikún B15.

Tàbí “ààfin.”

Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Tàbí “wíńdò.”

Tàbí “ló ní férémù onígun mẹ́rin.”

Tàbí “Ibi Àbáwọlé.”

Tàbí “Ibi Àbáwọlé.”

Tàbí “ààfin.”

Ní Héb., “ilé Gbọ̀ngàn.”

Tàbí “gọ̀bì.”

Tàbí “idẹ,” ní ibí yìí àti ní àwọn ibi tí ọ̀rọ̀ yìí ti fara hàn nínú orí yìí.

Tàbí “ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òpó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní ìyípo.”

Tàbí “gọ̀bì.”

Tàbí “gọ̀bì.”

Ibi Mímọ́ ni ibí yìí ń tọ́ka sí.

Tàbí “gúúsù.”

Ó túmọ̀ sí “Kí Ó [ìyẹn, Jèhófà] Fìdí Rẹ̀ Múlẹ̀ Gbọn-in.”

Tàbí “àríwá.”

Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Nínú Okun.”

Tàbí “agbada ńlá.”

Tàbí “ó jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní ìyípo.”

Nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 7.4 (ínǹṣì 2.9). Wo Àfikún B14.

Báàtì kan jẹ́ Lítà 22 (gálọ́ọ̀nù 5.81). Wo Àfikún B14.

Tàbí “kẹ̀kẹ́ omi.”

Tàbí “pa pọ̀ mọ́.”

Tàbí “pa pọ̀ mọ́.”

Tàbí “ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀.”

Tàbí “ẹ̀mú.”

Ìyẹn, Àjọyọ̀ Àtíbàbà.

Wo Àfikún B15.

Ní Héb., “ọmọ rẹ, tó máa jáde láti abẹ́nú rẹ.”

Tàbí “tí ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ sì gégùn-ún fún un.” Ìyẹn, ìbúra tó ní ègún nínú gẹ́gẹ́ bí ìyà tó máa jẹ ẹni tó bá búra èké tàbí tó dalẹ̀.

Ní Héb., “ègún.”

Ní Héb., “ègún.”

Ní Héb., “ẹni burúkú.”

Ní Héb., “olódodo.”

Tàbí “fìyà jẹ wọ́n.”

Tàbí “tata.”

Ní Héb., “ní ilẹ̀ àwọn ẹnubodè rẹ̀.”

Tàbí “ohun tó gbọ́ nípa rẹ.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Tàbí “fetí sí ohunkóhun tí wọ́n bá béèrè lọ́wọ́ rẹ.”

Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”

Ní Héb., “kẹjọ,” ìyẹn, ọjọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ́ méje kejì.

Tàbí “ààfin.”

Ní Héb., “àfipòwe.”

Tàbí “ààfin.”

Ní Héb., “wọn kò dára ní ojú rẹ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “Ilẹ̀ Tí Kò Dára fún Ohunkóhun.”

Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Tàbí “ààfin.”

Tàbí “Mílò.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “iyẹ̀pẹ̀ tí a kó jọ gègèrè.”

Tàbí “ẹ̀bùn ìgbéyàwó; nǹkan ìyàwó.”

Tàbí “mọ odi.”

Tàbí “Mílò.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “iyẹ̀pẹ̀ tí a kó jọ gègèrè.”

Tàbí “àwọn àlọ́.”

Tàbí “ẹgbẹ́ abánirìn.”

Ní Héb., “fara pa mọ́.”

Ní Héb., “kò sí ẹ̀mí kankan mọ́ nínú rẹ̀.”

Tàbí “ọ̀rọ̀.”

Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Tàbí “ààfin.”

Ní Héb., “ohun tó wá látọwọ́ Ọba Sólómọ́nì.”

Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.

Mínà kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jẹ́ gíráàmù 570. Wo Àfikún B14.

Ní Héb., “wá ojú.”

Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.

Tàbí “àwọn agẹṣin.”

Tàbí “àwọn agẹṣin.”

Tàbí kó jẹ́, “láti Íjíbítì àti Kúè; àwọn oníṣòwò ọba á rà wọ́n láti Kúè,” ó lè jẹ́ pé Sìlíṣíà ló ń tọ́ka sí.

Tàbí “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fẹ́ wọn, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ yín.”

Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Tàbí “àwọn ìyàwó rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”

Ní Héb., “ní kíkún.”

Ní Héb., “ké gbogbo ọkùnrin tó wà ní Édómù kúrò.”

Tàbí kó jẹ́, “gba ọmú lẹ́nu rẹ̀.”

Tàbí “akónilẹ́rù.”

Ní Héb., “pa.”

Ní Héb., “gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.”

Tàbí “Mílò.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “iyẹ̀pẹ̀ tí a kó jọ gègèrè.”

Ní Héb., “ní fìtílà.”

Tàbí “ọkàn rẹ.”

Ní Héb., “Àwọn ọjọ́.”

Tàbí “tó nira.”

Tàbí “àgbààgbà.”

Tàbí “àgbààgbà.”

Tàbí “ìránṣẹ́.”

Tàbí “ọmọńdinrín mi.”

Tàbí “àgbààgbà.”

Ní Héb., “àgọ́.”

Ní Héb., “àṣàyàn jagunjagun.”

Tàbí “mọ odi.”

Tàbí “mọ odi.”

Tàbí “ohun tó máa ṣẹlẹ̀.”

Tàbí “Ohun tó máa ṣẹlẹ̀.”

Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.

Tàbí “rọ.”

Tàbí “ohun tó máa ṣẹlẹ̀.”

Tàbí “tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ lójú.”

Tàbí “di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì.”

Tàbí “di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì.”

Tàbí “di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì.”

Tàbí “di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì.”

Ní Héb., “ló máa ń kún ọwọ́ rẹ̀.”

Ìyẹn, ohun tí a fi amọ̀ ṣe tó dà bí ìgò ńlá.

Tàbí “Báyìí-báyìí ni kí o sọ fún un.”

Tàbí “ère dídà.”

Ní Héb., “ké gbogbo ọkùnrin ilé Jèróbóámù kúrò.”

Ní Héb., “ẹnikẹ́ni tó ń tọ̀ sára ògiri.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn ọkùnrin.

Ní Héb., “ké.”

Ìyẹn, koríko etí omi.

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “Àwọn ọjọ́.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ààfin.”

Ní Héb., “àwọn sárésáré.”

Tí wọ́n tún ń pè ní Ábíjà.

Ní Héb., “fún un ní fìtílà.”

Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

Tàbí “ìyáàfin.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”

Tàbí “mọ odi; tún Rámà kọ́.”

Tàbí “sí ìpínlẹ̀.”

Tàbí “ààfin.”

Tàbí “Májẹ̀mú.”

Tàbí “májẹ̀mú.”

Tàbí “mímọ odi; títún Rámà kọ́.”

Tàbí “mọ odi; tún Gébà kọ́.”

Tàbí “mọ odi sí; tún kọ́.”

Ìyẹn, Nádábù, ọmọ Jèróbóámù.

Ní Héb., “ẹnikẹ́ni tó ń tọ̀ sára ògiri.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn ọkùnrin.

Tàbí “agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.”

Tàbí “ààfin.”

Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Ní Héb., “olúwa.”

Ó túmọ̀ sí “Ó Jẹ́ Ti Agbo Ilé Ṣémérì.”

Tàbí “tẹ́ńpìlì.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ọlọ́run Mi.”

Ní Héb., “tí mo dúró síwájú rẹ̀.”

Tàbí “Kí ló pa èmi àti ìwọ pọ̀, . . .?”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “ké àwọn wòlíì Jèhófà kúrò.”

Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.

Ní Héb., “tí mo dúró síwájú rẹ̀.”

Tàbí “ìtanùlẹ́gbẹ́.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “tiro.”

Tàbí kó jẹ́, “ó ti rìnrìn àjò.”

Tàbí “ṣe bíi wòlíì.”

Síà kan jẹ́ Lítà 7.33. Wo Àfikún B14.

Tàbí “àfonífojì.”

Tàbí “sán.”

Tàbí “ṣe ọkàn rẹ bí ọkàn ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn òun.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Ni Ìgbàlà.”

Ní Héb., “ó fi wọ́n rúbọ.”

Tàbí “àtíbàbà.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “àwọn àtíbàbà.”

Tàbí “pa àwọn ará Síríà ní ìpakúpa.”

Ìyẹn, ìgbà ìrúwé.

Ní Héb., “ka.”

Ìyẹn, ìgbà ìrúwé.

Tàbí “máa ń ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “yan àwọn ojú ọ̀nà fún ara rẹ ní.”

Tàbí “májẹ̀mú.”

“Àwọn ọmọ wòlíì” ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn wòlíì ti ń gba ìtọ́ni tàbí ẹgbẹ́ tó jẹ́ ti àwọn wòlíì.

Tàbí “mú ọ balẹ̀.”

Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Tàbí “ọkàn rẹ dí ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “ọkàn rẹ ló máa dí ọkàn rẹ̀.”

Ní Héb., “tí ìbànújẹ́ fi bá ẹ̀mí rẹ.”

Ní Héb., “gba ohun ìní rẹ̀.”

Ní Héb., “O ti ta ara rẹ.”

Ní Héb., “ẹnikẹ́ni tó ń tọ̀ sára ògiri.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn ọkùnrin.

Ní Héb., “ta ara rẹ̀.”

Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “ti.”

Tàbí “áńgẹ́lì.”

Tàbí “ta ọfà rẹ̀ láìfojú sun nǹkan kan.”

Ní Héb., “ní ibùdó.”

Tàbí kó jẹ́, “níbi tí àwọn aṣẹ́wó ti máa ń wẹ̀, àwọn ajá lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.”

Tàbí “ààfin.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́